April
Wednesday, April 1
[Jésù] sọ fún Pétérù pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! . . . Èrò èèyàn lò ń rò, kì í ṣe ti Ọlọ́run.”—Mát. 16:23.
Àwa náà ńkọ́? Ṣé èrò Ọlọ́run ló ń darí wa àbí èrò táyé ń gbé lárugẹ? Lóòótọ́, a lè má ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ àwọn ohun tá à ń rò lọ́kàn wa ńkọ́? Ṣé ohun tá à ń rò lọ́kàn bá ohun tí Jèhófà fẹ́ mu? Tá a bá fẹ́ kí èrò wa bá ti Jèhófà mu, àfi ká dìídì sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́wọ́ kejì, ó rọrùn gan-an láti máa ronú bíi tàwọn èèyàn ayé, kì í sì í pẹ́ tó fi máa ń mọ́ọ̀yàn lára. Ìdí ni pé àwọn tí ẹ̀mí ayé ń darí ló yí wa ká. (Éfé. 2:2) Yàtọ̀ síyẹn, ìmọtara-ẹni-nìkan ni ayé ń gbé lárugẹ, torí náà ó lè máa wù wá pé ká ṣe bíi tiwọn. Ká sòótọ́, kò rọrùn láti ní èrò Jèhófà, àmọ́ ó rọrùn gan-an láti máa ronú bíi tàwọn èèyàn ayé. Tá a bá jẹ́ kí èrò ayé máa darí wa, a lè di onímọtara-ẹni-nìkan, ká sì fẹ́ máa ṣe ohun tó wù wá. (Máàkù 7:21, 22) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká ní ‘èrò Ọlọ́run,’ ká má sì fàyè gba èrò èèyàn. w18.11 18 ¶1; 19 ¶3-4
Thursday, April 2
Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.—Mát. 3:17.
Ó dájú pé inú rẹ̀ máa dùn gan-an nígbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ láti ọ̀run nígbà mẹ́ta, tó sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ Jésù. Àkọ́kọ́ ni ìgbà tí Jésù ṣèrìbọmi nínú Odò Jọ́dánì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jòhánù Oníbatisí nìkan ló wà níbẹ̀, tó sì gbọ́ ohùn Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, nǹkan bí ọdún kan kí Jésù tó kú, àwọn àpọ́sítélì mẹ́ta gbọ́ tí Jèhófà sọ nípa Jésù pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà; ẹ fetí sí i.” (Mát. 17:5) Bákan náà, ní ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ikú Jésù, Jèhófà tún bá Ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. (Jòh. 12:28) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù mọ̀ pé àwọn èèyànkéèyàn máa parọ́ mọ́ òun, wọ́n á pe òun ní asọ̀rọ̀ òdì, òun á sì kú ikú ẹ̀sín, síbẹ̀ ó gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ dípò tara rẹ̀. (Mát. 26:39, 42) Bíbélì sọ pé Jésù ‘fara da òpó igi oró, ó sì tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú’ torí pé ó ń wá ojúure Jèhófà dípò tayé.—Héb. 12:2. w18.07 10-11 ¶15-16
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 9) Máàkù 14:3-9
Friday, April 3
Baba, tí o bá fẹ́, mú ife yìí kúrò lórí mi.—Lúùkù 22:42.
Kété lẹ́yìn tí Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, ó ṣe ohun kan tó fi hàn pé ó ní ìgboyà. Kí ló ṣe? Jésù gbà láti ṣe ohun tí Baba rẹ̀ fẹ́ kó ṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa fẹ̀sùn kàn án pé ó jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì, wọ́n á sì pa á. (Mát. 26:65, 66) Síbẹ̀, ó jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú kó lè sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, kó sì fi hàn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Yàtọ̀ síyẹn, á mú kó ṣeé ṣe fáwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jésù tún múra àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sílẹ̀ fún ohun tí wọ́n máa tó fojú winá rẹ̀. Jésù tún lo ìgboyà ní ti pé ohun táwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nílò ló gbájú mọ́ dípò kó máa ronú nípa ohun tó máa kojú. Lẹ́yìn tó jẹ́ kí Júdásì jáde, ó fi ìrántí ikú rẹ̀ lọ́lẹ̀. Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tó ṣe yẹn máa rán àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó máa tó di ẹni àmì òróró létí àǹfààní tí ẹbọ ìràpadà ṣe wọ́n àti àǹfààní tí wọ́n ní láti wọnú májẹ̀mú tuntun.—1 Kọ́r. 10:16, 17. w19.01 22 ¶7-8
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 9) Máàkù 11:1-11
Saturday, April 4
Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.—Jòh. 12:28.
Jèhófà dá Jésù lóhùn látọ̀run pé: “Mo ti ṣe é lógo, màá sì tún ṣe é lógo.” Jésù ní ìdààmú ọkàn torí ó mọ̀ pé wọ́n máa tó fìyà burúkú jẹ òun, wọ́n á sì pa òun ní ìpa ìka. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, òun gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́. (Mát. 26:38) Àmọ́ ohun tó jẹ ẹ́ lọ́kàn jù ni bó ṣe máa ṣe orúkọ Baba rẹ̀ lógo. Wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, Jésù sì ronú pé tí wọ́n bá pa òun lórí ẹ̀sùn yìí, ó ṣeé ṣe kíyẹn kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Bíi ti Jésù, ó lè máa dun àwa náà pé àwọn èèyàn ń kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa fojú pọ́n wa láìṣẹ̀ láìrò. Ó sì lè jẹ́ irọ́ táwọn alátakò ń pa mọ́ wa ló ń kó ìdààmú ọkàn bá wa. A lè máa ṣàníyàn pé àwọn nǹkan tí wọ́n ń sọ yìí máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún ọmọ rẹ̀ máa tù wá nínú gan-an. Ohun kan tó dájú hán-ún ni pé Jèhófà máa ṣe orúkọ rẹ̀ lógo.—Sm. 94:22, 23; Àìsá. 65:17. w19.03 11-12 ¶14-16
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 10) Máàkù 11:12-19
Sunday, April 5
Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ . . . jìyà tó pọ̀ . . . kí wọ́n sì pa òun.—Mát. 16:21.
Nígbà tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun máa jìyà, òun sì máa tó kú, ẹnu yà wọ́n gan-an torí wọ́n rò pé Jésù ló máa dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣàkóso lé wọn lórí. Ara Pétérù kò gbà á, ló bá sọ fún Jésù pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.” Àmọ́ Jésù fún un lésì pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.” (Mát. 16:22, 23; Ìṣe 1:6) Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín èrò Ọlọ́run àti èrò tí ayé Sátánì ń gbé lárugẹ. (1 Jòh. 5:19) Ọ̀pọ̀ nínú ayé gbà pé kò yẹ kéèyàn máa fìyà jẹ ara ẹ̀, irú èrò yìí sì ni Pétérù náà ní. Àmọ́ Jésù mọ̀ pé èrò Jèhófà yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Torí náà, èsì tí Jésù fún Pétérù fi hàn kedere pé èrò Jèhófà ni Jésù ní, kì í ṣe ti ayé. w18.11 18 ¶1-2
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 11) Máàkù 11:20–12:27, 41-44
Monday, April 6
Ẹ̀ ń kéde ikú Olúwa, títí á fi dé.—1 Kọ́r. 11:26.
Àwọn nǹkan kan wà tí Jèhófà máa ń kíyè sí bó ṣe ń wo ẹgbàágbèje èèyàn tó pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Kì í ṣe báwọn èèyàn ṣe pọ̀ nìkan ló ń kíyè sí, ó tún ń kíyè sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń kíyè sí àwọn tó ń wá lọ́dọọdún. Lára irú àwọn bẹ́ẹ̀ làwọn tó ń wá láìka inúnibíni tí wọ́n ń kojú sí. Àwọn míì sì wà tí kì í wá sáwọn ìpàdé ìjọ àmọ́ tí wọn kì í pa Ìrántí Ikú Kristi jẹ. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún máa ń kíyè sí àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi fúngbà àkọ́kọ́ torí pé wọ́n fẹ́ wá wo bá a ṣe ń ṣe é. Ó dájú pé inú Jèhófà ń dùn bó ṣe ń rí i tí ọ̀pọ̀ ń wá sí Ìrántí Ikú Kristi. (Lúùkù 22:19) Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà ni ohun tó mú kí wọ́n wá. Ó ṣe tán, ohun tó ń súnni ṣe nǹkan ló ṣe pàtàkì sí Jèhófà. Ǹjẹ́ ó máa ń wù wá láti gba ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà àti ètò rẹ̀?—Aísá. 30:20; Jòh. 6:45. w19.01 26 ¶1-3
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 12) Máàkù 14:1, 2, 10, 11; Mátíù 26:1-5, 14-16
Ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi
Lẹ́yìn Tí Oòrùn Bá Wọ̀
Tuesday, April 7
Kristi kú fún wa.—Róòmù 5:8.
Jésù múra tán láti kú fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ojoojúmọ́ ló tún máa ń ṣe ohun tó fi hàn pé ó fi ire wọn ṣáájú tiẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ ẹ́ gan-an, tó sì ní ìdààmú ọkàn. (Lúùkù 22:39-46) Bákan náà, bó ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ló máa ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, kì í ṣe ohun táwọn èèyàn lè ṣe fún un. (Mát. 20:28) Inú ẹgbẹ́ ará kan ṣoṣo tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú la wà, inú wa sì ń dùn bá a ṣe ń pe àwọn ẹni tuntun láti dara pọ̀ mọ́ wa. Síbẹ̀, àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lọ́kàn jù làwọn ‘tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́’ àmọ́ tí wọ́n ti di aláìṣiṣẹ́mọ́. (Gál. 6:10) A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn tá a bá ń fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n wá sípàdé, pàápàá jù lọ Ìrántí Ikú Kristi. Bíi ti Jèhófà àti Jésù, inú wa máa ń dùn gan-an tí irú àwọn bẹ́ẹ̀ bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.— Mát. 18:14. w19.01 29 ¶12, 14; 30 ¶15
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 13) Máàkù 14:12-16; Mátíù 26:17-19 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 14) Máàkù 14:17-72
Wednesday, April 8
Èyí túmọ̀ sí ara mi. . . . Èyí túmọ̀ sí “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi.”—Mát. 26:26-28.
Nígbà tí Jésù dá ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀, ó lo búrẹ́dì àti wáìnì tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe Ìrékọjá tán. Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé ohun èlò méjèèjì náà ṣàpẹẹrẹ ara rẹ̀ pípé àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó máa fi rúbọ nítorí wọn. Ó dájú pé kò ní ya àwọn àpọ́sítélì náà lẹ́nu pé ọ̀nà ráńpẹ́ ni Jésù gbà fi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí lọ́lẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Oṣù díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn. Jésù lọ sílé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, ìyẹn Lásárù, Màtá àti Màríà. Níbẹ̀, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ dípò kí Màtá jókòó tì wọ́n, kùrùkẹrẹ bó ṣe máa se oúnjẹ rẹpẹtẹ fún Jésù ló ń ṣe. Èyí mú kí Jésù tọ́ ọ sọ́nà, ó sì fún un nímọ̀ràn pé kò pọn dandan kó filé pọntí fọ̀nà rokà. (Lúùkù 10:40-42) Ìtọ́ni yìí kan náà ni Jésù fúnra ẹ̀ fi sílò ní wákàtí díẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀. Dípò kí Jésù ṣètò oúnjẹ rẹpẹtẹ fún ìrántí ikú rẹ̀, ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ló ṣètò. w19.01 20-21 ¶3-4
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 14) Máàkù 15:1-47
Thursday, April 9
Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní.—Jòh. 17:5.
Jèhófà jí Jésù dìde, ó sì gbé e sí “ipò gíga” lọ́run. Ó tún fún Jésù lóhun tí kò tíì fún ẹ̀dá kankan rí ṣáájú ìgbà yẹn, ìyẹn àìleèkú! (Fílí. 2:9; 1 Tím. 6:16) Ẹ ò rí i pé ọ̀nà àgbàyanu ni Jèhófà gbà san Jésù lẹ́san torí ìṣòtítọ́ rẹ̀! Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa wá ojúure àwọn èèyàn ayé yìí? Ẹ jẹ́ ká máa fi sọ́kàn pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń fojúure hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, ó sì sábà máa ń san wọ́n lẹ́san láwọn ọ̀nà tí wọn ò lérò. Ta ló mọ ọ̀nà àrà tí Jèhófà máa gbà bù kún wa lọ́jọ́ iwájú? Ní báyìí ná, ìṣòro tàbí àdánwò yòówù ká máa kojú nínú ayé yìí, ẹ jẹ́ ká máa rántí nígbà gbogbo pé ayé yìí máa tó kọjá lọ. (1 Jòh. 2:17) Àmọ́, Jèhófà Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ‘kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ wa àti ìfẹ́ tí a fi hàn fún orúkọ rẹ̀.’—Héb. 6:10. w18.07 11 ¶17-18
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 15) Mátíù 27:62-66 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 16) Máàkù 16:1
Friday, April 10
Mò ń gbàdúrà nípa wọn . . . kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan.—Jòh. 17:20, 21.
Ohun tó jẹ Jésù lọ́kàn lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ni bí wọ́n ṣe máa wà níṣọ̀kan. Ohun tó béèrè nínú àdúrà tó gbà pẹ̀lú wọn jẹ́ kó ṣe kedere pé ó wù ú pé káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan bí òun àti Bàbá òun ṣe jẹ́ ọ̀kan. Tí wọ́n bá wà níṣọ̀kan, ó máa hàn gbangba pé Jèhófà ló rán Jésù wá sáyé kó lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìfẹ́ ló máa jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù wà níṣọ̀kan, á sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wọ́n. (Jòh. 13:34, 35) Jésù tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wà níṣọ̀kan nígbà tí wọ́n ń jẹun pa pọ̀ lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú wọn. Ìdí ni pé ẹnu wọn ò kò, wọn ò sì wà níṣọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, lórí ìjókòó níbẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn jiyàn “lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ,” kì í sì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tírú ẹ̀ máa wáyé nìyẹn. (Lúùkù 22:24-27; Máàkù 9:33, 34) Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jákọ́bù àti Jòhánù sọ fún Jésù pé kó fi àwọn sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì rẹ̀ nínú Ìjọba rẹ̀.—Máàkù 10:35-40. w18.06 8 ¶1-2
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 16) Máàkù 16:2-8
Saturday, April 11
Ọkùnrin á . . . fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́ ìyàwó rẹ̀, wọ́n á sì di ara kan.—Jẹ́n. 2:24.
Jèhófà fẹ́ káwọn tọkọtaya nífẹ̀ẹ́ ara wọn débi pé wọ́n á ṣera wọn lọ́kan, wọn ò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun yà wọ́n. (Mát. 19:3-6) Ìwà ìkà gbáà ni tí ẹnikẹ́ni nínú wọn bá ṣe àgbèrè, irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò sì fi ìfẹ́ hàn. Abájọ tí òfin keje fi pa á láṣẹ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè. (Diu. 5:18) Ṣe lẹni tó hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ ‘ṣẹ̀ sí Ọlọ́run,’ ọ̀dàlẹ̀ sì ni. (Jẹ́n. 39:7-9) Ẹ wo bí irú ìwà bẹ́ẹ̀ ṣe máa dun ẹnì kejì rẹ̀ tó. Ohun kan sì ni pé ọgbẹ́ tírú ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń dá síni lọ́kàn kì í tètè jinná. Jèhófà tún nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé gan-an, kò sì fẹ́ kí wọ́n fìyà jẹ wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà pàṣẹ fún àwọn òbí pé kí wọ́n pèsè ohun tí àwọn ọmọ wọn nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Wọ́n gbọ́dọ̀ máa lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní Òfin Ọlọ́run, kí wọ́n sì mú káwọn ọmọ náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Diu. 6:6-9; 7:13) Àwọn ọmọ ṣeyebíye ju dúkìá lọ, torí náà ojú gidi ni Jèhófà fẹ́ káwọn òbí fi máa wo àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì mọyì wọn torí pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n.—Sm. 127:3. w19.02 21 ¶5, 7
Sunday, April 12
Ọlọ́run . . . máa wá mọ ìwà títọ́ mi.—Jóòbù 31:6.
Jóòbù mọ̀ pé Ọlọ́run máa san òun lẹ́san, ìyẹn sì mú kó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́. Ó mọ̀ pé inú Ọlọ́run ń dùn sí òun bí òun ṣe ń hùwà tó tọ́. Bí Jóòbù tiẹ̀ dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa san òun lẹ́san. Ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní yìí ló mú kó máa ṣe ohun tó tọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù jẹ́ aláìpé, síbẹ̀ kò bọ́hùn, ìyẹn sì mú kí inú Jèhófà dùn sí i, ó sì bù kún un jìngbìnnì. (Jóòbù 42:12-17; Ják. 5:11) Ó dájú pé Jèhófà tún máa san án lẹ́san tó jùyẹn lọ lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà ò tíì yí pa dà. (Mál. 3:6) Tá a bá ń fi sọ́kàn pé Jèhófà mọyì bá a ṣe jẹ́ adúróṣinṣin, ìyẹn á jẹ́ kí ìrètí ọjọ́ iwájú túbọ̀ dá wa lójú. (1 Tẹs. 5:8, 9) Nígbà míì, ó lè dà bíi pé ìwọ nìkan lò ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, má jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́, ẹgbàágbèje àwọn olóòótọ́ kárí ayé bíi tìẹ ló ń hùwà tó tọ́. O tún máa wà lára àwọn olóòótọ́ ọkùnrin àti obìnrin tí Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin kódà lójú ikú.—Héb. 11:36-38; 12:1. w19.02 7 ¶15-16
Monday, April 13
Kí èrò gbogbo yín ṣọ̀kan, kí ẹ máa bára yín kẹ́dùn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ ará, kí ẹ lójú àánú, kí ẹ sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.—1 Pét. 3:8.
Lẹ́yìn tá a ti ṣe Ìrántí Ikú Kristi, á dáa kí kálukú bi ara rẹ̀ pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ fìwà jọ Jésù tó bá di pé kí n máa fìfẹ́ hàn? Ṣé ire àwọn míì máa ń jẹ mí lọ́kàn, àbí tara mi nìkan ni mò ń rò? Ṣé mi ò máa retí pé káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ, àbí mo máa ń gba tiwọn rò?’ Ǹjẹ́ kí gbogbo wa túbọ̀ máa fara wé Jésù ká sì máa gba tàwọn míì rò. Láìpẹ́ a ò ní ṣe Ìrántí Ikú Kristi mọ́. Tí Jésù bá “dé” nígbà ìpọ́njú ńlá, ó máa kó gbogbo “àwọn àyànfẹ́” tó ṣẹ́ kù lọ sí ọ̀run. Tíyẹn bá ti ṣẹlẹ̀, a ò ní ṣe Ìrántí Ikú Kristi mọ́. (1 Kọ́r. 11:26; Mát. 24:31) Tá ò bá tiẹ̀ ṣe Ìrántí Ikú Kristi mọ́, ó dájú pé àá ṣì máa rántí ètò pàtàkì tí Jésù fi lọ́lẹ̀ yìí. Á jẹ́ ká máa rántí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ga jù lọ, ìgboyà àti ìfẹ́ tí Jésù fi hàn. w19.01 25 ¶17-19
Tuesday, April 14
Inú rẹ máa ń dùn sí òtítọ́ tó ti ọ̀kan ẹni wá; kọ́ inú mi lọ́hùn-ún ní ọgbọ́n tòótọ́.—Sm. 51:6.
Ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ ìlera ṣàkàwé bó ṣe yẹ kára èèyàn le nípa tẹ̀mí. Àkọ́kọ́, kára èèyàn lè jí pépé, ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore, kó sì máa ṣe eré ìmárale déédéé. Lọ́nà kan náà, ó ṣe pàtàkì ká máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé tá a bá fẹ́ dúró sán-ún nípa tẹ̀mí, a sì gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó fi hàn pé lóòótọ́ la nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Èyí gba pé ká máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò, ká sì máa sọ ohun tá a gbà gbọ́ fún àwọn míì. (Róòmù 10:8-10; Ják. 2:26) Ìkejì, ẹnì kan lè máa ta kébékébé, kó sì rò pé koko lara òun le, síbẹ̀ kó jẹ́ pé onírúurú àrùn ló ti kọ́lé sí i lára. Lọ́nà kan náà, ẹnì kan lè máa ṣe tibí ṣe tọ̀hún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kó sì gbà pé ìgbàgbọ́ òun lágbára, síbẹ̀ kó jẹ́ pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti gbà á lọ́kàn. (1 Kọ́r. 10:12; Ják. 1:14, 15) Ká máa fi sọ́kàn pé gbogbo ọ̀nà ni Sátánì ń wá láti sọ èrò ọkàn wa dìbàjẹ́. w19.01 15 ¶4-5
Wednesday, April 15
Ìwọ náà, lọ ṣe ohun kan náà. —Lúùkù 10:37.
Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé èmi náà máa ń fàánú hàn sáwọn èèyàn bíi ti ọkùnrin ará Samáríà yìí?’ (Lúùkù 10:30-35) ‘Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ máa fàánú hàn sáwọn tó ń jìyà? Bí àpẹẹrẹ, ṣé mo lè ṣèrànwọ́ fáwọn àgbàlagbà, àwọn opó tó fi mọ́ àwọn ọmọ táwọn òbí wọn ò sí nínú òtítọ́? Ṣé mo máa ń kíyè sáwọn “tí ó soríkọ́,” kí n sì wá ọ̀nà láti “sọ̀rọ̀ ìtùnú” fún wọn?’ (1 Tẹs. 5:14; Ják. 1:27) Tá a bá ń ṣàánú àwọn míì, à ń fún wọn ní nǹkan nìyẹn, Jésù sí sọ pé a máa láyọ̀ tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, tá a bá ń fàánú hàn sáwọn èèyàn, a máa múnú Jèhófà dùn. (Ìṣe 20:35; Héb.13:16) Ọba Dáfídì sọ ohun tí Jèhófà máa ṣe fún ẹni tó bá ń ṣàánú àwọn míì, ó sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ, yóò sì pa á mọ́ láàyè. A óò máa pè é ní aláyọ̀ ní ilẹ̀ ayé.” (Sm. 41:1, 2) Tá ò bá jẹ́ kó sú wa láti máa ṣàánú, Jèhófà máa fàánú hàn sáwa náà, ìyẹn sì máa jẹ́ ká láyọ̀ títí láé.—Ják. 2:13. w18.09 19 ¶11-12
Thursday, April 16
Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́.—Àìsá. 41:10.
Arábìnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Yoshiko gbọ́ ìròyìn burúkú kan. Dókítà tó ń tọ́jú rẹ̀ sọ fún un pé kò lè lò ju oṣù mélòó kan lọ táá fi kú. Báwo lọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára rẹ̀? Arábìnrin Yoshiko rántí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó fẹ́ràn gan-an, ìyẹn ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Dípò kó káyà sókè, ṣe ló sọ fún dókítà náà pé ọkàn òun balẹ̀ torí pé Jèhófà di òun lọ́wọ́ mú. Ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ló mú kí arábìnrin wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láìmikàn. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí kan náà lè mú kí ọkàn wa balẹ̀ tá a bá tiẹ̀ kojú àwọn ìṣòro tó lágbára. Nígbà tí Jèhófà gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ ọ̀rọ̀ yẹn, ṣe ló fi ń tu àwọn Júù tó máa lọ sígbèkùn Bábílónì nínú. Àmọ́ o, kì í ṣe torí àwọn Júù yẹn nìkan ni Jèhófà ṣe mú kí ọ̀rọ̀ yẹn wà lákọọ́lẹ̀, ó tún fẹ́ kó ṣàǹfààní fáwọn tó ń sìn ín látìgbà yẹn títí dòní. (Aísá. 40:8; Róòmù 15:4) Ní báyìí, à ń gbé láwọn “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” Torí náà, a nílò ọ̀rọ̀ ìṣírí tó wà nínú ìwé Aísáyà ju ti ìgbàkígbà rí lọ.—2 Tím. 3:1. w19.01 2 ¶1-2
Friday, April 17
Tí aláìgbàgbọ́ náà bá pinnu láti lọ, jẹ́ kó máa lọ.—1 Kọ́r. 7:15.
Bí àwọn méjèèjì bá tiẹ̀ pínyà, tọkọtaya ni wọ́n ṣì jẹ́. Tí wọ́n bá ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n ṣì máa ní àwọn ìṣòro kan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ìdí kan tó fi dáa káwọn méjèèjì wà pa pọ̀, ó ní: “Ọkọ tí kò gbà gbọ́ ni a sọ di mímọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀, aya tí kò sì gbà gbọ́ ni a sọ di mímọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú arákùnrin náà; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn ọmọ yín ì bá jẹ́ aláìmọ́ ní ti gidi, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n jẹ́ mímọ́.” (1 Kọ́r. 7:14) Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló pinnu pé àwọn ò ní fi ẹnì kejì wọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ sílẹ̀ láìka àwọn ìṣòro tó lágbára tí wọ́n ní sí. Wọ́n gbà pé ìfaradà àwọn lérè gan-an, pàápàá nígbà tí ẹnì kejì náà di onígbàgbọ́ bíi tiwọn. (1 Kọ́r. 7:16; 1 Pét. 3:1, 2) Kárí ayé, pàápàá nínú ìjọ àwa èèyàn Jèhófà, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló ṣe ara wọn lọ́kan. Kò sí àní-àní pé àwọn tọkọtaya bẹ́ẹ̀ wà ní ìjọ yín. Àpẹẹrẹ àtàtà làwọn tọkọtaya yìí jẹ́ torí pé àwọn ọkọ nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn dénú, bẹ́ẹ̀ sì làwọn aya ń bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún àwọn ọkọ wọn. Wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó àwọn.—Héb. 13:4. w18.12 14 ¶18-19
Saturday, April 18
Jèhófà Ọlọ́run wá gbin ọgbà kan sí Édẹ́nì, . . . ó sì fi ọkùnrin tó dá síbẹ̀.—Jẹ́n. 2:8.
Édẹ́nì túmọ̀ sí “Ìtura,” ó sì dájú pé lóòótọ́ ni ọgbà yẹn tura. Ọgbà náà rẹwà gan-an, oúnjẹ pọ̀ níbẹ̀, àlàáfíà sì wà láàárín èèyàn àtàwọn ẹranko. (Jẹ́n. 1:29-31) Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ọgbà” làwọn Gíríìkì máa ń pè ní pa·raʹdei·sos. Nígbà tí ìwé Cyclopædia tí M’Clintock àti Strong ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa pa·raʹdei·sos, ó sọ pé: “Ọgbà kan tó fẹ̀ dáadáa, tí kò sóhun tó lè pani lára níbẹ̀, tó rẹwà gan-an, tó sì ní àwọn igi ńláńlá tí ọ̀pọ̀ nínú rẹ̀ ń so èso. Àwọn odò tó mọ́ tó sì tutù minimini rọra ń ṣàn gba inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ìgalà àtàwọn àgùntàn rọra ń jẹko lẹ́bàá odò náà.” (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 2:15, 16.) Irú Párádísè yẹn ni Ọlọ́run fi Ádámù àti Éfà sí, wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì pàdánù ojú rere rẹ̀. Bí wọ́n ṣe pàdánù Párádísè nìyẹn, tí wọ́n sì tún fi du àtọmọdọ́mọ wọn. (Jẹ́n. 3:23, 24) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí èèyàn kankan nínú ọgbà náà, ó jọ pé ọgbà náà wà títí dìgbà Ìkún Omi ọjọ́ Nóà. w18.12 3-4 ¶3-5
Sunday, April 19
Èmi, Jèhófà, . . . ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.—Àìsá. 48:17.
Àwọn òbí máa ń sapá láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè níwà ọmọlúàbí. Wọ́n máa ń kọ́ wọn láti jẹ́ olóòótọ́, kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ kára, kí wọ́n sì máa gba tàwọn míì rò. Táwọn ọmọ náà bá tójú bọ́, tí wọ́n sì kúrò ńlé, wọ́n á lómìnira láti pinnu ohun tí wọ́n fẹ́. Tí wọ́n bá gbẹ̀kọ́ dáadáa, tí wọ́n sì fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣe àwọn ìpinnu tí wọn ò ní kábàámọ̀. Wọn ò sì ní tọrùn bọ wàhálà àtàwọn ìṣòro táwọn míì máa ń kó sí. Bíi ti òbí kan tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀, Jèhófà náà fẹ́ káyé wa ládùn kó lóyin. (Aísá. 48:18) Ìdí nìyẹn tó fi fún wa láwọn ìlànà nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà àti bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn míì. Ó fẹ́ ká máa fojú tóun fi ń wo nǹkan wò ó, ká sì máa fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. Àwọn ìlànà yìí ò ká wa lọ́wọ́ kò rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń jẹ́ ká lè ronú jinlẹ̀, ká sì lo làákàyè wa. (Sm. 92:5; Òwe 2:1-5; Aísá. 55:9) Èyí máa jẹ́ ká ṣe àwọn ìpinnu táá fún wa láyọ̀, táá sì jẹ́ ká gbádùn ayé wa. (Sm. 1:2, 3) Ká sòótọ́, àá jàǹfààní tá a bá ń jẹ́ kí èrò Jèhófà darí wa. w18.11 19-20 ¶7-8
Monday, April 20
Wọ́n ń sọ̀rọ̀ yín láìdáa.—1 Pét. 4:4.
Tá a bá fẹ́ máa bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn tí kò sin Jèhófà kó èèràn ràn wá. Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà yí pa dà. Àwọn kan fara mọ́ ohun tá a gbà gbọ́, àwọn míì sì di alátakò paraku. Àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn ọmọ iléèwé wa àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lè fẹ́ ká jọ máa ṣe àwọn ayẹyẹ kan. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ lọ́wọ́ sí àwọn àṣà àtàwọn àjọ̀dún tí inú Jèhófà ò dùn sí? Ohun tá a lè ṣe ni pé ká máa ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀. A lè ṣe ìwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa nípa ibi tí irú àwọn àjọ̀dún bẹ́ẹ̀ ti ṣẹ̀ wá. Tá a bá ń rántí ìdí tí àwọn àjọ̀dún yẹn ò fi bá Ìwé Mímọ́ mu, á dá wa lójú pé a ṣì ń rìn lójú ọ̀nà “tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.” (Éfé. 5:10) Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a sì gbà pé òótọ́ lohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a ò ní ‘wárìrì nítorí ènìyàn.’—Òwe 29:25. w18.11 11 ¶10, 12
Tuesday, April 21
Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, Jèhófà sì ń mú kí gbogbo ohun tó bá ṣe yọrí sí rere. —Jẹ́n. 39:23.
Nígbà tí nǹkan bá ṣàdédé yí pa dà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn débi pé a ò ní rí nǹkan míì rò ju àwọn ìṣòro wa lọ. Nígbà tí Jósẹ́fù kojú ìṣòro, kò kárísọ débi tí ìrẹ̀wẹ̀sì á fi bò ó mọ́lẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, ó sì fi ìyókù sílẹ̀ fún Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣiṣẹ́ kára nígbà tó wà lọ́dọ̀ Pọ́tífárì, ohun tó sì ṣe náà nìyẹn nígbà tó wà lẹ́wọ̀n. Gbogbo ohun tí ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀wọ̀n bá ní kó ṣe ló máa ń ṣe. (Jẹ́n. 39:21, 22) Bíi ti Jósẹ́fù, àwa náà lè bá ara wa láwọn ipò kan tó jẹ́ pé ìwọ̀nba lohun tá a lè ṣe sí i. Síbẹ̀, tá a bá ṣe sùúrù, tá a sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, Jèhófà máa bù kún wa. (Sm. 37:5) Ká sòótọ́, ‘ọkàn wa lè dàrú’ nígbà míì, síbẹ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa dúró tì wá. (2 Kọ́r. 4:8) Ó dájú pé tá a bá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn wa, Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé! w18.10 29 ¶11, 13
Wednesday, April 22
Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀. —Héb. 6:10.
Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tí ẹnì kan tó o mọ̀, tó o sì bọ̀wọ̀ fún bá gbàgbé orúkọ ẹ tàbí tí kò dá ẹ mọ̀? Kò sẹ́ni tírú ẹ̀ máa ṣe tí kò ní dùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé a máa ń fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá, kí wọ́n sì kà wá sí, ó ṣe tán àpọ́nlé lara ń fẹ́. Àmọ́ kì í ṣe irú àpọ́nlé bẹ́ẹ̀ nìkan la máa ń wá, a tún máa ń fẹ́ káwọn èèyàn mọ bá a ṣe jẹ́ kí wọ́n sì yẹ́ wa sí torí ohun tá a ti gbé ṣe. (Núm. 11:16; Jóòbù 31:6) Ṣùgbọ́n tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàṣejù torí pé a fẹ́ káwọn èèyàn mọyì wa. Ìyẹn lè mú ká máa ṣe ohun tí kò tọ́ torí a fẹ́ kí wọ́n gba tiwa. Ẹ̀mí burúkú táyé Sátánì ń gbé lárugẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í ràn wá, débi pé àwa náà lè fẹ́ lókìkí, ká sì lẹ́nu láwùjọ. Tọ́rọ̀ bá ti rí bẹ́ẹ̀, a ò ní lè fún Jèhófà Baba wa ọ̀run ní ìjọsìn tó yẹ ẹ́.—Ìṣí. 4:11. w18.07 7 ¶1-2
Thursday, April 23
Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.—1 Jòh. 5:19.
Kò yà wá lẹ́nu pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ lè mú káwọn tó wà nípò àṣẹ máa “purọ́.” (1 Tím. 4:1, 2) Irọ́ táwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń pa ló burú jù torí ẹni tó bá gbà wọ́n gbọ́ lè pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹnì kan bá gba àwọn ẹ̀kọ́ èké gbọ́ tó sì ń ṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run kórìíra, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun. (Hós. 4:9) Jésù mọ̀ pé onírọ́ burúkú làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé rẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi sọ ọ́ kò wọ́n lójú pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! nítorí pé ẹ̀yin a máa la òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ kọjá láti sọ ẹnì kan di aláwọ̀ṣe, nígbà tí ó bá sì di ọ̀kan, ẹ̀yin a sọ ọ́ di olùdojúkọ ewu Gẹ̀hẹ́nà [ìyẹn ìparun ayérayé] ní ìlọ́po méjì ju ara yín lọ.” (Mát. 23:15) Dẹndẹ ọ̀rọ̀ ni Jésù fi bá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn wí. Kódà Jésù sọ fún wọn pé, ‘àti ọ̀dọ̀ Èṣù baba wọn tó jẹ́ apànìyàn’ ni wọ́n ti wá.—Jòh. 8:44. w18.10 7 ¶5-6
Friday, April 24
Aláyọ̀ ni yín tí àwọn èèyàn bá pẹ̀gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni sí yín, . . . nítorí mi.—Mát. 5:11.
Kí nìdí tí Jésù fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó fi kún un pé: “Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run; nítorí ní ọ̀nà yẹn ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ó wà ṣáájú yín.” (Mát. 5:12) Nígbà tí wọ́n na àwọn àpọ́sítélì, tí wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, wọ́n “bá ọ̀nà wọn lọ kúrò níwájú Sànhẹ́dírìn, wọ́n ń yọ̀.” Kì í ṣe pé ó wù wọ́n láti jìyà, àmọ́ wọ́n ń láyọ̀ “nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ [Jésù].” (Ìṣe 5:41) Bákan náà lónìí, àwa èèyàn Jèhófà ń fara da onírúurú àtakò nítorí orúkọ Jésù, síbẹ̀ à ń láyọ̀. (Ják. 1:2-4) Bíi tàwọn àpọ́sítélì Jésù, inú wa kì í dùn nígbà táwọn èèyàn bá ń ṣenúnibíni sí wa, àmọ́ ó da wa lójú pé tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin, Jèhófà máa fún wa nígboyà ká lè fara dà á. Tí inú Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀” bá ń dùn sí wa, a máa láyọ̀ báwọn èèyàn tiẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa tàbí táwọn mọ̀lẹ́bí wa ń takò wá torí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí.—1 Tím. 1:11. w18.09 21 ¶18-20
Saturday, April 25
Wàhálà àti ìbànújẹ́ ló kún inú wọn.—Sm. 90:10.
“Àwọn àkókò lílekoko” là ń gbé, wàhálà tí ọ̀pọ̀ sì ń bá yí kọjá àfẹnusọ. Èyí ti mú kí ayé sú ọ̀pọ̀ èèyàn. (2 Tím. 3:1-5) Kódà ìwádìí kan fi hàn pé ohun tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800,000) èèyàn ló ń gbẹ̀mí ara wọn lọ́dọọdún, ìyẹn fi hàn pé ó kéré tán èèyàn kan ń gbẹ̀mí ara rẹ̀ láàárín ìṣẹ́jú kan. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn Kristẹni kan lónìí náà ti gbẹ̀mí ara wọn torí ìṣòro tí wọ́n ní. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń kojú àwọn ìṣòro tó ń tánni lókun, ó sì yẹ ká gbé wọn ró tìfẹ́tìfẹ́. Àwọn kan ń kojú àtakò àti ìfiniṣẹ̀sín. Wọ́n ń fìtínà àwọn míì ní ibiṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ àṣelàágùn táwọn kan ń ṣe ti mú kí wọ́n ṣàárẹ̀. Ìṣòro ìdílé làwọn míì ń bá yí, bóyá torí pé ọkọ tàbí aya wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ìṣòro yìí ti mú kí àárẹ̀ bá àwọn kan nínú ìjọ, kí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì. w18.09 13 ¶3, 5
Sunday, April 26
Kò sí ohun tó ń mú inú mi dùn bíi kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.—3 Jòh. 4.
Àwọn òbí Kristẹni lè bá Jèhófà ṣiṣẹ́ tí wọ́n bá ń gbin iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sọ́kàn àwọn ọmọ wọn. Àwọn òbí kan ti ṣe bẹ́ẹ̀, èyí sì ti mú káwọn ọmọ wọn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alákòókò kíkún, kódà níbi tó jìnnà sílé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ti di míṣọ́nnárì, àwọn míì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà níbi tí àìní gbé pọ̀, àwọn míì sì ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárò lè máa sọ àwọn òbí yìí torí ọ̀nà àwọn ọmọ wọn tó jìn sílé, síbẹ̀ àwọn òbí tó lẹ́mìí ìfara-ẹni-rúbọ máa ń fún àwọn ọmọ wọn níṣìírí láti máa bá iṣẹ́ ìsìn náà nìṣó. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń rí i táwọn ọmọ wọn ń fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, èyí sì ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn òbí yìí ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hánà tó sọ pé òun fún Jèhófà ní Sámúẹ́lì ọmọ òun. Kò sí àní-àní pé àwọn òbí yìí kà á sí àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti bá Jèhófà ṣiṣẹ́ lọ́nà yìí.—1 Sám. 1:28. w18.08 24 ¶4
Monday, April 27
Ó máa ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba ọ̀run.—Mát. 19:23.
Jésù ò sọ pé wọn ò lè wọ Ìjọba ọ̀run rárá. Ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹ̀yin òtòṣì, nítorí pé tiyín ni Ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 6:20) Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn òtòṣì ló máa fara mọ́ ẹ̀kọ́ Jésù tí wọ́n á sì gba ìbùkún tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ àwọn òtòṣì ni kò tẹ̀ lé Jésù. Kókó ibẹ̀ ni pé kì í ṣe bóyá ẹnì kan jẹ́ olówó tàbí tálákà ló ń pinnu bí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣe máa rí. Inú wa dùn pé a láwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, olówó àti tálákà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń sìn ín tọkàntọkàn. Ìwé Mímọ́ gba àwọn ọlọ́rọ̀ níyànjú pé “kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run.” (1 Tím. 6:17-19) Lẹ́sẹ̀ kan náà, Bíbélì gba gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run níyànjú pé ká ṣọ́ra fún ìfẹ́ owó yálà a jẹ́ olówó tàbí tálákà. (1 Tím. 6:9, 10) Kò sí àní-àní pé tá a bá ń wo àwọn ará wa bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n, a ò ní máa fi bí wọ́n ṣe lówó tó pinnu irú ẹni tí wọ́n jẹ́. w18.08 10-11 ¶11-12
Tuesday, April 28
Ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run. —Jém. 4:7.
Ó dájú pé ó ń wù wá láti fi hàn pé a mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wa láti jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ọ̀kan nínú ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká ya ara wa sí mímọ́ fún un. A ti pinnu láti kórìíra ohun búburú. Yàtọ̀ síyẹn, à ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa, a sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn torí pé àwọn náà jẹ́ ti Jèhófà. (Róòmù 12:10) Bíbélì ṣèlérí pé: “Jèhófà ò ní pa àwọn èèyàn rẹ̀ tì.” (Sm. 94:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá ò lérò lè ṣẹlẹ̀ sí wa, síbẹ̀ ìlérí tí Jèhófà ṣe yìí dájú. Kódà tá a bá kú, Jèhófà ò ní gbàgbé wa. (Róòmù 8:38, 39) Nítorí pé “tí a bá wà láàyè tàbí tí a bá kú, a jẹ́ ti Jèhófà.” (Róòmù 14:8) À ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Jèhófà máa jí gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti kú dìde lọ́jọ́ iwájú. (Mát. 22:32) Kódà ní báyìí, ọ̀pọ̀ ìbùkún là ń gbádùn. Bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ ló rí, pé “aláyọ̀ ni orílẹ̀-èdè tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, àwọn èèyàn tí ó ti yàn láti jẹ́ ohun ìní rẹ̀.”—Sm. 33:12. w18.07 26 ¶18-19
Wednesday, April 29
Ohun gbogbo ló bófin mu, àmọ́ kì í ṣe ohun gbogbo ló ṣàǹfààní. Ohun gbogbo ló bófin mu, àmọ́ kì í ṣe ohun gbogbo ló ń gbéni ró. —1 Kọ́r. 10:23.
Àwọn kan lè ronú pé ìpinnu ara ẹni ni béèyàn ṣe máa kàwé tó, irú iṣẹ́ tó máa ṣe àtohun tó máa fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe, torí náà ohun tó bá wu kálukú ló lè ṣe tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ti gbà á. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n tọ́ka sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì lórí ọ̀rọ̀ oúnjẹ, pé: “Èé ṣe tí ó fi ní láti jẹ́ pé ẹ̀rí-ọkàn ẹlòmíràn ní ń ṣèdájọ́ òmìnira mi?” (1 Kọ́r. 10:29) Lóòótọ́, kálukú ló máa pinnu ohun tó máa ṣe. Síbẹ̀, ó yẹ ká rántí pé ó níbi tí òmìnira wa mọ àti pé kò sí ìpinnu téèyàn ṣe tí kì í lérè. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi sọ ọ̀rọ̀ ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lómìnira láti pinnu ohun tá a máa ṣe, àwọn nǹkan pàtàkì míì wà tó yẹ ká ronú lé. w18.04 10 ¶10
Thursday, April 30
Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì pa dà sọ́dọ̀ yín.—Mál. 3:7.
Àwọn Kristẹni kan lónìí sọ pé àwọn ń sin Jèhófà, àmọ́ wọ́n tún ń lọ́wọ́ sí àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra. (Júúdà 11) Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè máa lọ sípàdé déédéé, kó sì máa kópa tó jọjú lóde ẹ̀rí. Síbẹ̀, èròkérò lè ti gba ẹni yẹn lọ́kàn tàbí kó jẹ́ pé ìrònú bó ṣe máa ní tibí ní tọ̀hún ló gbà á lọ́kàn tàbí kó tiẹ̀ kórìíra arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ̀. (1 Jòh. 2:15-17; 3:15) Irú àwọn èrò burúkú bẹ́ẹ̀ lè mú kó hùwàkiwà. Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn lè má mọ ohun tá à ń rò tàbí ohun tá à ń ṣe. Àmọ́ ká rántí pé Jèhófà rí ohun gbogbo, ó sì máa mọ̀ tá ò bá sìn ín tọkàntọkàn. (Jer. 17:9, 10) Tá a bá ṣàṣìṣe, Jèhófà ṣì máa ń mú sùúrù fún wa. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fìfẹ́ rọ àwọn tó ṣi ẹsẹ̀ gbé pé: “Ẹ padà sọ́dọ̀ mi.” Jèhófà mọ̀ pé a láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tá à ń bá yí, síbẹ̀ ó fẹ́ ká sapá ká lè borí wọn. (Aísá. 55:7) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà náà máa dúró tì wá, á sì fún wa ní okun tá a nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí ká lè “kápá” èrò òdì.—Jẹ́n. 4:7. w18.07 18 ¶5-6