May
Friday, May 1
Kí [ẹ] nífẹ̀ẹ́ àjèjì.—Diu. 10:19.
Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ ló ti ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì torí pé wọ́n ń wá ibi ìsádi. O lè kọ́ bí wọ́n ṣe ń kí àwọn èèyàn lédè wọn. Yàtọ̀ síyẹn, o lè kọ́ díẹ̀ nínú èdè wọn kó o lè sọ ohun táá fà wọ́n lọ́kàn mọ́ra. O lè tipa bẹ́ẹ̀ darí wọn lọ sí ìkànnì jw.org, kí wọ́n lè wo àwọn fídíò àtàwọn ìtẹ̀jáde tó wà lédè wọn. Ká lè túbọ̀ já fáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, Jèhófà ti ṣètò Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ fún wa. Àwọn nǹkan tá à ń kọ́ nípàdé yìí máa ń jẹ́ ká túbọ̀ nígboyà láti ṣe ìpadàbẹ̀wò ká sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀yin òbí, ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa dáhùn lọ́rọ̀ ara wọn, ìyẹn á jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látàrí ìdáhùn àtọkànwá tí wọ́n gbọ́ lẹ́nu àwọn ọmọ wa.—1 Kọ́r. 14:25. w18.06 22-23 ¶7-9
Saturday, May 2
Ẹ tẹ́wọ́ gba ara yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ṣe tẹ́wọ́ gbà yín. —Róòmù 15:7.
Ó yẹ ká máa rántí pé “àjèjì” ni gbogbo wa jẹ́ sí Ọlọ́run tẹ́lẹ̀. (Éfé. 2:12) Àmọ́ Jèhófà fà wá mọ́ra torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Hós. 11:4; Jòh. 6:44) Jésù náà sì tẹ́wọ́ gbà wá. Ṣe ló dà bí ìgbà tó ṣílẹ̀kùn fún wa ká lè di ara ìdílé Ọlọ́run. Jésù fìfẹ́ tẹ́wọ́ gbà wá, kò sì tẹ́ńbẹ́lú wa láìka pé a jẹ́ aláìpé, torí náà kò yẹ káwa náà fojú tẹ́ńbẹ́lú ẹnikẹ́ni. A mọ̀ pé ẹ̀tanú, rògbòdìyàn àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà á túbọ̀ máa pọ̀ sí i bí òpin ayé búburú yìí ṣe ń sún mọ́lé. (Gál. 5:19-21; 2 Tím. 3:13) Àmọ́ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń jẹ́ kí ọgbọ́n tó wá láti òkè máa darí wa, ọgbọ́n yìí máa ń jẹ́ ká wá àlàáfíà, ká má sì ṣe ojúsàájú. (Ják. 3:17, 18) Inú wa máa ń dùn láti ní àwọn ọ̀rẹ́ láti ilẹ̀ míì, à ń kọ́ àṣà wọn kódà a tún máa ń kọ́ èdè wọn. Èyí ti jẹ́ kí àlàáfíà wa dà bí odò, kí òdodo wa sì dà bí ìgbì òkun.—Aísá. 48:17, 18. w18.06 12 ¶18-19
Sunday, May 3
Pẹ̀lú ẹsẹ̀ yín tí a wọ̀ ní bàtà, [ẹ] fi ìmúratán kéde ìhìn rere àlàáfíà.—Éfé. 6:15.
Ọmọ ogun Róòmù kan ò lè lọ sójú ogun láìwọ bàtà rẹ̀. Awọ mẹ́ta tó nípọn tí wọ́n rán pa pọ̀ ni wọ́n fi ṣe bàtà náà. Wọ́n ṣe bàtà náà lọ́nà táá mú kí ọmọ ogun kan lè rìn dáadáa, kó má sì ta á lẹ́sẹ̀. Bó ṣe jẹ́ pé bàtà táwọn ọmọ ogun Róòmù wọ̀ ló máa ń gbé wọn lọ sójú ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni bàtà ìṣàpẹẹrẹ táwa Kristẹni wọ̀ máa ń jẹ́ ká lè mú ìhìn rere àlàáfíà lọ fáwọn èèyàn. (Aísá. 52:7; Róòmù 10:15) Síbẹ̀, ó gba ìgboyà ká tó lè sọ ìhìn rere náà fáwọn èèyàn. Ọmọ ogún [20] ọdún ni ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Bo, ó sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, ẹ̀rù máa ń bà mí láti wàásù fáwọn ọmọ kíláàsì mi torí pé ojú máa ń tì mí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ ohun tó ń jẹ́ kójú tì mí. Àmọ́ ní báyìí, inú mi máa ń dùn láti wàásù fún wọn.” Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lónìí ti rí i pé táwọn bá múra sílẹ̀ dáadáa, ó túbọ̀ máa ń rọrùn fún wọn láti wàásù. w18.05 29 ¶9-11
Monday, May 4
[Ẹ máa] so èso púpọ̀.—Jòh. 15:8.
Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Mo fi àlàáfíà mi fún yín.” (Jòh 14:27) Báwo ni ẹ̀bùn yìí ṣe ń mú ká máa so èso? Bá a ṣe ń fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ọkàn wa máa ń balẹ̀ torí a mọ̀ pé inú Jèhófà àti Jésù ń dùn sí ohun tá à ń ṣe. (Sm. 149:4; Róòmù 5:3, 4; Kól. 3:15) Lẹ́yìn tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé òun fẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀, ó ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì ṣe tán láti fara wọn jìn fáwọn míì. (Jòh. 15:11-13) Lẹ́yìn náà, Jésù sọ fún wọn pé: “Mo pè yín ní ọ̀rẹ́.” Àbí ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù! Àmọ́ kí làwọn àpọ́sítélì gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù nìṣó? Wọ́n gbọ́dọ̀ ‘máa bá a lọ láti máa so èso.’ (Jòh. 15:14-16) Ní nǹkan bí ọdún méjì ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù pàṣẹ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa wàásù, pé, ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’ ” (Mát. 10:7) Torí náà, lálẹ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú wọn, ó ní kí wọ́n máa fara dà á nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.—Mát. 24:13; Máàkù 3:14. w18.05 20-21 ¶15-16
Tuesday, May 5
Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.—Gál. 6:7.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ kan, rí i pé ìjọsìn Jèhófà ló gbawájú nígbèésí ayé rẹ. Ìyẹn ni pé bí ọwọ́ rẹ ṣe máa tẹ àwọn àfojúsùn tẹ̀mí ló yẹ kó gbà ẹ́ lọ́kàn. Ó dájú pé wàá rí àwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ tí wọ́n láwọn ń gbádùn ara wọn, wọ́n tiẹ̀ lè máa rọ̀ ẹ́ pé kíwọ náà wá dara pọ̀ mọ́ wọn. Má ṣe jẹ́ káwọn ojúgbà ẹ tì ẹ́ síbi tí kò yẹ. Ó ṣe pàtàkì kó o jẹ́ kí wọ́n mọ ìpinnu tó o ti ṣe. Kí lo lè ṣe táwọn ojúgbà ẹ ò fi ní sọ ẹ́ dà bí wọ́n ṣe dà? Àkọ́kọ́, yẹra fáwọn nǹkan tó máa mú kó o ṣe ohun tó lòdì sí ìpinnu rẹ. (Òwe 22:3) Ìkejì, má gbàgbé pé àwọn tó bá lọ́wọ́ sí nǹkan burúkú máa tìka àbámọ̀ bọnu. Ìkẹta, jẹ́ káwọn míì mọ ìṣòro tó o ní, kó o sì gbàmọ̀ràn. Tó o bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti gbàmọ̀ràn àwọn òbí ẹ àtàwọn míì tó dàgbà nípa tẹ̀mí nínú ìjọ. (1 Pét. 5:5, 6) Ṣé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ débi pé wàá lè gbàmọ̀ràn tó dáa táwọn míì bá fún ẹ? w18.04 28-29 ¶14-16
Wednesday, May 6
Ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin títí mo fi máa dé. Ẹni tó bá ṣẹ́gun, tó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ mi títí dé òpin ni màá fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè. —Ìfi. 2:25, 26.
Nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù bá àwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà Kékeré sọ, ó gbóríyìn fún wọn torí iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń bá ìjọ Tíátírà sọ̀rọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn náà: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ àti ìfẹ́, ìgbàgbọ́, iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìfaradà rẹ àti pé àwọn iṣẹ́ rẹ tí ò ń ṣe báyìí pọ̀ ju èyí tí o ṣe níbẹ̀rẹ̀.” (Ìṣí. 2:19) Kì í ṣe bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ṣe ń tẹ̀ síwájú nìkan ni Jésù sọ, ó tún gbóríyìn fún wọn torí pé wọ́n ní àwọn ànímọ́ rere tó mú kí wọ́n máa ṣe dáadáa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan wà nínú ìjọ yẹn tó nílò ìbáwí, síbẹ̀ ṣe ló kọ́kọ́ fún wọn níṣìírí, ọ̀rọ̀ ìṣírí náà ló sì fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Ìṣí. 2:27, 28) Ṣé ẹ ò gbàgbé pé Jésù tó jẹ́ orí ìjọ là ń sọ̀rọ̀ ẹ̀? Ṣé a lè sọ pé ó jẹ wá ní gbèsè ọpẹ́ torí ohun tá a ṣe fún un? Síbẹ̀, Jésù máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn jẹ́ fún àwọn alàgbà! w19.02 16 ¶10
Thursday, May 7
Júdásì àti Sílà . . . fi ọ̀pọ̀ àsọyé gba àwọn ará níyànjú, wọ́n sì fún wọn lókun.—Ìṣe 15:32.
Bí ìgbìmọ̀ olùdarí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe ń fún àwọn ará níṣìírí náà ni wọ́n ń fún àwọn tó ń múpò iwájú níṣìírí. Wọ́n rán Pétérù àti Jòhánù pé kí wọ́n lọ gbàdúrà fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́, kí wọ́n lè rí ẹ̀mí mímọ́ gbà. (Ìṣe 8:5, 14-17) Ẹ wo bí inú Fílípì àtàwọn tó wàásù fún ṣe máa dùn tó pé ìgbìmọ̀ olùdarí mọyì àwọn! Lónìí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fún ẹgbẹ́ ará kárí ayé níṣìírí títí kan àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn tó ń sìn ní pápá. Kí nìyẹn ti yọrí sí? Bó ṣe rí lára àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà ló rí lára wa. À ń yọ̀ torí ìṣírí tá à ń rí gbà. Yàtọ̀ síyẹn, lọ́dún 2015, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ìwé kan jáde tá a pè ní Jọ̀wọ́ Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà, ìwé yìí sì ti fún ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé níṣìírí láti pa dà sínú ètò Jèhófà. w18.04 19 ¶18-20
Friday, May 8
Ẹ ó mọ òtítọ́, òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.—Jòh. 8:32.
Àwọn kan lè ronú pé á dáa téèyàn bá lè ṣe ohun tó wù ú láìsí ẹni tó ń yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. Òótọ́ kan ni pé àǹfààní wà nínú kéèyàn lè ṣe ohun tó wù ú, àmọ́ ewu tún wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo bí ayé ṣe máa rí ká sọ pé kò sí òfin kankan, táwọn èèyàn sì ń ṣe ohun tó wù wọ́n láìsí ẹni tó ń yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò. Ìwé The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ní ọ̀pọ̀ ìlú, wọ́n máa ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òfin. Àwọn òfin yìí máa ń fún àwọn èèyàn lómìnira, ó sì tún máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè lo òmìnira náà.” Ká sòótọ́, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ òfin làwọn èèyàn ti ṣe, bẹ́ẹ̀ sì làwọn lọ́yà àtàwọn adájọ́ tí wọ́n ń túmọ̀ òfin pọ̀ jáǹtìrẹrẹ. Ohun méjì ni Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè gbádùn òmìnira tòótọ́: Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó fi kọ́ni, ìkejì sì ni pé ká di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá ní òmìnira tòótọ́. Àmọ́ òmìnira kúrò lọ́wọ́ kí ni? Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń dá ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. . . . Bí Ọmọ bá dá yín sílẹ̀ lómìnira, ẹ ó di òmìnira ní ti gidi.”—Jòh. 8:34, 36. w18.04 6-7 ¶13-14
Saturday, May 9
Ẹ máa bára yín kẹ́dùn.—1 Pét. 3:8.
Inú wa máa ń dùn tá a bá wà pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa tí wọ́n sì ń gba tiwa rò. Ìdí sì ni pé wọ́n máa ń fi ara wọn sí ipò wa kí wọ́n lè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa àti bí nǹkan ṣe rí lára wa. Wọ́n máa ń fòye mọ ohun tá a nílò, ìgbà míì sì wà tí wọ́n máa ń pèsè ẹ̀ kódà ká tó béèrè. A máa ń mọyì àwọn tí ọ̀rọ̀ wa jẹ lọ́kàn tí wọ́n sì ń ‘bá wa kẹ́dùn.’ Ó yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni máa gba tàwọn míì rò. Àmọ́ ká sòótọ́, ó lè gba pé ká túbọ̀ sapá ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí kan ni pé aláìpé ni wá. (Róòmù 3:23) Torí pé aláìpé ni wá, tara wa nìkan la sábà máa ń rò. Yàtọ̀ síyẹn, kì í rọrùn fáwọn kan láti gba tàwọn míì rò torí bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà tàbí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn rí. Ohun míì tún ni pé ìwà àwọn tó yí wa ká lè ràn wá. Bí àpẹẹrẹ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, wọn kì í gba tàwọn míì rò rárá. (2 Tím. 3:1, 2) Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀, àá túbọ̀ mọ bá a ṣe lè máa gba tàwọn míì rò. w19.03 14 ¶1-3
Sunday, May 10
Dáàbò bo ọkàn rẹ.—Òwe 4:23.
Òfin Kẹwàá pa á láṣẹ pé a ò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò, ká má ṣe jẹ́ kí ọkàn wa máa fà sí nǹkan àwọn míì. (Diu. 5:21; Róòmù 7:7) Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan ni Jèhófà fi òfin yẹn kọ́ àwa èèyàn rẹ̀, ó fẹ́ ká kíyè sí ohun tá à ń rò àti ohun tí ọkàn wa ń fà sí. Ó mọ̀ pé èròkerò ló máa ń mú kéèyàn hu ìwàkiwà. Àpẹẹrẹ ẹnì kan tó ṣe irú ẹ̀ ni Ọba Dáfídì. Kò sẹ́ni tí kò mọ̀ pé èèyàn dáadáa ni Dáfídì, àmọ́ ìgbà kan wà tó ṣojúkòkòrò ìyàwó oníyàwó. Ojúkòkòrò yẹn mú kó dẹ́ṣẹ̀, ó bá obìnrin náà ṣàgbèrè, ọ̀rọ̀ náà sì doyún. (Ják. 1:14, 15) Dáfídì wá gbìyànjú láti ti oyún náà sọ́rùn ọkọ rẹ̀. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ó pa ọkọ obìnrin yẹn. (2 Sám. 11:2-4; 12:7-11) Kì í ṣe bá a ṣe rí lóde nìkan ni Jèhófà ń rí, ó tún mọ ẹni tá a jẹ́ nínú, ó sì mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. (1 Sám. 16:7) Torí náà, kò sóhun tẹ́nì kan ń rò tàbí tó ń ṣe tó pa mọ́ lójú Ọlọ́run. Bó ti wù kó rí, ibi tá a dáa sí ni Jèhófà ń wò. Àmọ́, ó fẹ́ ká kíyè sí ibi tá a kù sí àti ohun tá à ń rò, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ àá kó sínú ẹ̀ṣẹ̀.—2 Kíró. 16:9; Mát. 5:27-30. w19.02 21 ¶9; 22 ¶11
Monday, May 11
Ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin oníwà pẹ̀lẹ́ ayé . . . ẹ wá ìwà pẹ̀lẹ́. —Sef. 2:3.
Bíbélì sọ pé Mósè “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Núm. 12:3) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ọ̀lẹ ni Mósè àti pé kò lè dá ìpinnu ṣe, àbí pé ó máa ń bẹ̀rù táwọn míì bá ta kò ó? Àwọn kan máa ń ronú pé ojo lẹni tó bá lọ́kàn tútù, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Akínkanjú ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni Mósè, ó sì fìgboyà gbé ìgbésẹ̀ nígbà tó yẹ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti kojú ọba Íjíbítì tó jẹ́ alágbára. Yàtọ̀ síyẹn, ó darí àwọn èèyàn tó ṣeé ṣe kí wọ́n tó mílíọ̀nù mẹ́ta gba inú aginjù, ó sì mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. A lè má kojú àwọn ìṣòro tí Mósè kojú, àmọ́ ó dájú pé ojoojúmọ́ là ń kojú àwọn ipò tàbí àwọn èèyàn tó lè mú kó ṣòro fún wa láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù. Síbẹ̀, Bíbélì sọ ìdí kan tó fi yẹ ká sapá láti ní ànímọ́ yìí. A rí ìdí yìí nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe pé, “àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” (Sm. 37:11) Ṣé o lè sọ pé ọlọ́kàn tútù ni ẹ́? Ṣé àwọn míì sì gbà pé lóòótọ́ lo jẹ́ ọlọ́kàn tútù? w19.02 8 ¶1-2
Tuesday, May 12
Àwọn tó ń sọ pé . . . ohun tó burú dára gbé.—Àìsá. 5:20.
Àtìgbà tí Jèhófà ti dá àwa èèyàn ló ti fún wa ní ẹ̀rí ọkàn. Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ṣe ni wọ́n sá pa mọ́. Èyí fi hàn pé ẹ̀rí ọkàn wọn ń dà wọ́n láàmú lẹ́yìn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀. Tí ẹ̀rí ọkàn ẹnì kan ò bá ṣiṣẹ́ dáadáa, ńṣe lẹni náà dà bí ọkọ̀ ojú omi tó wà lójú agbami àmọ́ tí ẹ̀rọ atọ́nisọ́nà ìyẹn kọ́ńpáàsì tó ní kò ṣiṣẹ́ dáadáa. Ó léwu gan-an tí awakọ̀ kan bá ń fi kọ́ńpáàsì tí kò ṣiṣẹ́ dáadáa darí ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ torí pé atẹ́gùn àti ìgbì òkun lè darí ọkọ̀ náà gba ibòmíì. Àmọ́ tí kọ́ńpáàsì ọkọ̀ kan bá ń ṣiṣẹ́ dáadáa, ìyẹn á jẹ́ kí ọkọ̀ ojú omi náà gba ojú ọ̀nà tó tọ́. Lọ́nà kan náà, ẹ̀rí ọkàn wa dà bíi kọ́ńpáàsì tó ń darí ọkọ̀ ojú omi kan. Ẹ̀rí ọkàn wa máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ó sì máa ń darí wa sí ọ̀nà tó yẹ. Àmọ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa tó lè tọ́ wa sọ́nà, kó sì darí wa síbi tó yẹ, ó gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Tí ẹnì kan ò bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ dáadáa, ẹ̀rí ọkàn náà ò ní kìlọ̀ fún un tó bá fẹ́ ṣe ohun tí kò tọ́. (1 Tím. 4:1, 2) Irú ẹ̀rí ọkàn bẹ́ẹ̀ lè mú kó dà bíi pé “ohun tí ó burú dára.” w18.06 16 ¶1-3
Wednesday, May 13
Ẹ má sì jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí máa darí yín.—Róòmù 12:2.
A gbọ́dọ̀ wà lójúfò torí pé àwọn èrò kan wà táyé ń gbé lárugẹ lọ́nà tí kò fi bẹ́ẹ̀ hàn sójú táyé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn oníròyìn kan lè fọgbọ́n gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú kan, kéèyàn má sì mọ̀. Àwọn ìròyìn míì máa ń dá lórí báwọn kan ṣe rí towó ṣe tẹ́nu wọn sì tólẹ̀ láwùjọ. Àwọn fíìmù àtàwọn ìwé kan máa ń kọ́ àwọn èèyàn pé ara wọn tàbí ìdílé wọn ló yẹ kí wọ́n fi ṣáájú ohunkóhun míì, wọ́n sì lè ṣe é lọ́nà táá fi dà bíi pé ohun tí wọ́n sọ yẹn mọ́gbọ́n dání. Àmọ́ èrò bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé téèyàn bá fi ti Jèhófà ṣáájú nìkan ló tó lè gbádùn ayé rẹ̀, kí ìdílé rẹ̀ sì láyọ̀. (Mát. 22:36-39) Èyí ò túmọ̀ sí pé a ò lè gbádùn eré ìnàjú. Síbẹ̀, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mo tètè máa ń fura tí eré kan bá ń gbé èrò ayé lárugẹ kódà tí ò bá ṣe tààràtà? Ṣé mo máa ń ṣọ́ra fáwọn ìwé tàbí eré tó lè gbin èrò òdì sọ́kàn èmi àtàwọn ọmọ mi? Ṣé mo máa ń jẹ́ káwọn ọmọ mi mọ èrò Jèhófà dáadáa, débi pé èrò ayé tí wọ́n ń gbọ́ tí wọ́n sì ń rí kò ní nípa lórí wọn?’ w18.11 22 ¶18-19
Thursday, May 14
Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ. —Àìsá. 41:10.
Bí Jèhófà ṣe ń kíyè sí wa tó sì ń fìfẹ́ hàn sí wa jẹ́ ká mọ̀ pé lóòótọ́ ló wà pẹ̀lú wa. Ẹ gbọ́ ohun tó sọ tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an àti pé kò fọ̀rọ̀ wa ṣeré. Jèhófà sọ pé: “Ìwọ ṣe iyebíye ní ojú mi, a kà ọ́ sí ẹni tí ó ní ọlá, èmi fúnra mi sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.” (Aísá. 43:4) Kò sóhun náà láyé àti lọ́run tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ àtimáa nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń sìn ín. Adúróṣinṣin ni Jèhófà, kò sì ní yẹhùn. (Aísá. 54:10) Kì í ṣe pé Jèhófà ń ṣèlérí pé òun ò ní jẹ́ ká kojú ìṣòro rárá. Dípò bẹ́ẹ̀, kò ní jẹ́ kí àwọn ìṣòro tó dà bí “odò” bò wá mọ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní jẹ́ kí èyí tó dà bí “ọwọ́ iná” jó wa run. Ó fi dá wa lójú pé òun máa wà pẹ̀lú wa, òun á sì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti la àwọn ìṣòro náà kọjá. Ọ̀nà wo ló máa gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ó máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ tá a bá kojú ìṣòro, àá sì lè jẹ́ adúróṣinṣin, kódà lójú ikú. (Aísá. 41:13; 43:2) Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a sì gbà pé ó ‘máa wà pẹ̀lú wa,’ a ò ní bẹ̀rù, àá sì fìgboyà kojú ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú. w19.01 3 ¶4-6
Friday, May 15
Ọ̀pọ̀ nǹkan ni èèyàn ń gbèrò nínú ọkàn rẹ̀, àmọ́ ìmọ̀ràn Jèhófà ni yóò borí.—Òwe 19:21.
Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ó ṣeé ṣe kí àwọn olùkọ́ rẹ, àwọn agbani-nímọ̀ràn àtàwọn míì ti lè fún ẹ nímọ̀ràn pé kó o lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga, kó o lè níṣẹ́ gidi lọ́wọ́. Àmọ́, nǹkan ọ̀tọ̀ ni Jèhófà gbà ẹ́ níyànjú pé kó o fayé ẹ ṣe. Jèhófà fẹ́ kó o fojú sí ẹ̀kọ́ rẹ dáadáa nígbà tó o ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ girama, kó o lè bójú tó ara rẹ lẹ́yìn tó o bá jáde. (Kól. 3:23) Àmọ́ tó bá di pé kó o ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, Jèhófà rọ̀ ẹ́ pé kó o fi ìlànà òun sílò, kó o sì máa rántí ohun tó fẹ́ káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. (Mát. 24:14) Jèhófà mọ ibi tí ayé yìí ń forí lé, ó sì mọ̀gbà tó máa wá sópin. (Aísá. 46:10; Mát. 24:3, 36) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà mọ̀ wá ju bá a ṣe mọra wa lọ, òun nìkan ló mọ ohun tó máa jẹ́ káyé wa ládùn kó lóyin, àtohun tó lè mú kéèyàn kábàámọ̀. Torí náà, kò sí bí ìmọ̀ràn àwọn èèyàn ṣe lè bọ́gbọ́n mu tó, tí kò bá bá ìlànà Ọlọ́run mu, òtúbáńtẹ́ ni, kò sọ́gbọ́n nínú rẹ̀. w18.12 19 ¶1-2
Saturday, May 16
Ẹni burúkú ò ní sí mọ́.—Sm. 37:10.
Dípò bẹ́ẹ̀, “àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Ọlọ́run tún mú kí Dáfídì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sm. 37:11, 29; 2 Sám. 23:2) Báwo làwọn ìlérí yìí ṣe rí lára àwọn tó fẹ́ ṣèfẹ́ Ọlọ́run? Àwọn ìlérí yẹn jẹ́ kó túbọ̀ dá wọn lójú pé táwọn olódodo nìkan bá ń gbé láyé, ayé máa pa dà di Párádísè bíi ti ọgbà Édẹ́nì. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kẹ̀yìn sí Jèhófà, wọn ò sì jọ́sìn rẹ̀ mọ́. Torí náà, Jèhófà gba àwọn ará Bábílónì láyè láti ṣẹ́gun wọn, wọ́n run ilẹ̀ wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ wọn lẹ́rú. (2 Kíró. 36:15-21; Jer. 4:22-27) Síbẹ̀, àwọn wòlíì Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé lẹ́yìn àádọ́rin (70) ọdún, àwọn èèyàn náà máa pa dà sí ilẹ̀ wọn. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ní ìmúṣẹ, wọ́n sì tún kan àwa náà lónìí torí ayé yìí ṣì máa di Párádísè. w18.12 4 ¶9-10
Sunday, May 17
Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, èrò mi sì ga ju èrò yín.—Àìsá. 55:9.
Ẹ gbọ́ ná, nínú ìmọ̀ràn táyé ń fúnni àti ti Bíbélì, èwo ló máa ṣe wá láǹfààní lónìí? Jésù sọ pé “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mát. 11:19) Ká sòótọ́, ìtẹ̀síwájú ti bá ìmọ̀ ẹ̀rọ torí pé ojoojúmọ́ ni wọ́n ń gbé àwọn nǹkan tuntun jáde. Síbẹ̀, wọn ò lè yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń fa ìbànújẹ́ lónìí, irú bí ogun, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìwà ọ̀daràn. Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò rí ohun tó burú nínú ìṣekúṣe. Àmọ́ ọ̀pọ̀ gbà pé ìṣekúṣe ti ba nǹkan jẹ́ gan-an, torí pé ó ń tú ìdílé ká, ó sì ń fa onírúurú àrùn àtàwọn ìṣòro míì. Lọ́wọ́ kejì, àwa Kristẹni tá à ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run máa ń gbádùn ìdílé aláyọ̀, ìlera tó dáa, a sì tún ń gbádùn àlàáfíà àti ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará wa kárí ayé. (Aísá. 2:4; Ìṣe 10:34, 35; 1 Kọ́r. 6:9-11) Ǹjẹ́ èyí ò fi hàn kedere pé èrò Jèhófà ga ju tayé lọ fíìfíì? w18.11 20 ¶8-10
Monday, May 18
Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́.—1 Kọ́r. 15:33.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń sapá gan-an kí àárín àwa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa lè gún, a sì máa ń ṣenúure sí wọn, síbẹ̀ a ò ní pa òfin Jèhófà tì torí pé a fẹ́ tẹ́ wọn lọ́rùn. Ó ṣe kedere pé àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà nìkan ló yẹ kó jẹ́ ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́. Gbogbo àwọn tó ń rìn nínú òtítọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́. (Aísá. 35:8; 1 Pét. 1:14-16) Nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, gbogbo wa la ṣe àwọn àyípadà kan ká lè máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Kódà, àyípadà ńlá làwọn kan tiẹ̀ ṣe. Èyí ó wù kó jẹ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ìwà ìbàjẹ́ tó kúnnú ayé yìí má bàa sọ wá di aláìmọ́. Kí lá jẹ́ ká yẹra fún ìwà àìmọ́ àti ìṣekúṣe? Ó yẹ ká máa ronú nípa ohun tó ná Jèhófà kó lè sọ wá di mímọ́, ìyẹn ẹ̀jẹ̀ iyebíye Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi. (1 Pét. 1:18, 19) Torí náà, tá a bá fẹ́ máa jẹ́ mímọ́ nìṣó lójú Jèhófà, àfi ká máa rántí nígbà gbogbo pé ohun iyebíye ni ìràpadà Jésù tí Jèhófà fi wẹ̀ wá mọ́. w18.11 11 ¶10-11
Tuesday, May 19
Màá dúró de Ọlọ́run ìgbàlà mi. Ọlọ́run mi yóò gbọ́ mi.—Míkà 7:7.
Ọ̀pọ̀ àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gbà pé téèyàn bá pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó máa láyọ̀ láìka ìyípadà èyíkéyìí tó bá wáyé. Àpẹẹrẹ wọn ti jẹ́ ká rí i pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tá a sì ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé, a máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Kódà, a lè wá rí i pé àwọn ìyípadà tó ṣẹlẹ̀ sí wa ti mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ìgbàkigbà ni nǹkan lè yí pa dà fún wa nínú ayé yìí. Àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní lè yí pa dà, ó sì lè jẹ́ àìsàn kan ló máa ṣàdédé yọjú tàbí kí nǹkan yí pa dà nínú ìdílé wa. Àmọ́ ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ lásìkò tó o nílò rẹ̀ gẹ́lẹ́. (Héb. 4:16; 1 Pét. 5:6, 7) Àmọ́ ní báyìí ná, ṣe gbogbo ohun tágbára rẹ gbé nínú ipò èyíkéyìí. Máa gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì fi gbogbo ohun tó kù sílẹ̀ fún Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá ní ìbàlẹ̀ ọkàn láìka ìyípadà èyíkéyìí tó lè wáyé nígbèésí ayé rẹ. w18.10 30 ¶17; 31 ¶19, 22
Wednesday, May 20
[Jèhófà] mọ ẹ̀dá wa, Ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.—Sm. 103:14.
Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì nípa bí Jèhófà ṣe gba tàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rò. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí bí Jèhófà ṣe gba ti Sámúẹ́lì rò, tó sì ràn án lọ́wọ́ láti jíṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run fún Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà bó ṣe wà nínú 1 Sámúẹ́lì 3:1-18. Nínú Òfin Mósè, Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn àgbàlagbà, pàápàá àwọn tó bá ń múpò iwájú. (Ẹ́kís. 22:28; Léf. 19:32) Torí náà, báwo ló ṣe máa rọrùn tó fún Sámúẹ́lì láti lọ bá Élì kó sì kéde ìdájọ́ Ọlọ́run fún un? Ó dájú pé kò ní rọrùn! Kódà Bíbélì sọ pé Sámúẹ́lì “fòyà láti sọ fún Élì nípa àfihàn náà.” Àmọ́, Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere sí Élì pé òun lòun ń pe Sámúẹ́lì. Èyí ló mú kí Élì fúnra ẹ̀ pe Sámúẹ́lì, tó sì pàṣẹ fún un pé kó “[má ṣe] fi ọ̀rọ̀ kan pa mọ́” fún òun. Sámúẹ́lì ṣègbọràn, ó sì “sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un.” Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì bá ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tí Élì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ mu. (1 Sám. 2:27-36) Ìtàn yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń gba tèèyàn rò àti pé ọgbọ́n rẹ̀ ò láàlà. w18.09 23 ¶2; 24 ¶4-5
Thursday, May 21
Jèhófà, ta ló lè jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ? . . . Ẹni tó ń . . . sọ òtítọ́ nínú ọkàn rẹ̀.—Sm. 15:1, 2.
Irọ́ ti gbalẹ̀ gbòde lónìí. Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Y. Bhattacharjee sọ pé: “Irọ́ pípa ti di bárakú fáwọn èèyàn.” Àwọn èèyàn sábà máa ń parọ́ kí wọ́n lè dáàbò bo ara wọn tàbí kí wọ́n lè gbé ara wọn ga lójú àwọn míì. Ó sì lè jẹ́ torí kí wọ́n má bàa jìyà ìwàkíwà tí wọ́n hù tàbí kí wọ́n lè jẹ èrè tabua nídìí iṣẹ́ wọn. Àpilẹ̀kọ náà tún sọ pé: “Irọ́ rọ àwọn kan lọ́rùn débi pé kò sírú irọ́ tí wọn ò lè pa, kò sì sẹ́ni tí wọn ò lè parọ́ fún, yálà ẹni náà jẹ́ àjèjì, ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, ọ̀rẹ́ wọn tàbí èèyàn wọn.” Kí ni irọ́ táwọn èèyàn ń pa yìí máa ń yọrí sí? Lákọ̀ọ́kọ́, kì í jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán ara wọn mọ́, ó sì máa ń ba àjọṣe àárín àwọn èèyàn jẹ́. Dáfídì gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Ìwọ ní inú dídùn sí òtítọ́ ní ìhà inú.” (Sm. 51:6) Dáfídì mọ̀ pé téèyàn bá máa sọ òtítọ́, àtinú ọkàn lọ́hùn-ún ló ti máa ń wá. Torí náà, gbogbo ìgbà làwa Kristẹni tòótọ́ máa ń ‘bá ara wa sọ òtítọ́ lẹ́nì kìíní-kejì.’—Sek. 8:16. w18.10 7 ¶4; 8 ¶9-10; 10 ¶19
Friday, May 22
Ó darí wọn láìséwu, wọn ò sì bẹ̀rù ohunkóhun.—Sm. 78:53.
Ó ṣeé ṣe kí iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta nígbà tí wọ́n máa kúrò ní Íjíbítì lọ́dún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn ọmọdé wà láàárín wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àgbàlagbà, àwọn aláìlera títí kan àwọn aláàbọ̀ ara. Ẹni tó bá máa darí adúrú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ láti Íjíbítì gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó lóye, tó sì ń gba tẹni rò. Irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an nìyẹn, ó sì lo Mósè láti gbé àwọn ànímọ́ yìí yọ. Torí náà, ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń fi Íjíbítì tó jẹ́ ibì kan ṣoṣo tí wọ́n mọ̀ sílẹ̀. (Sm. 78:52) Kí ni Jèhófà ṣe tó mú kọ́kàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì balẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà ṣètò wọn sí àwùjọ-àwùjọ, wọ́n sì dà bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun. (Ẹ́kís. 13:18) Irú ètò yìí jẹ́ kó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú pé Jèhófà ló ń darí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àmì kan táá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun wà pẹ̀lú wọn. Bíbélì sọ pé ó fi “àwọsánmà ṣamọ̀nà wọn ní ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ iná ní gbogbo òru.” (Sm. 78:14) Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù torí mo wà pẹ̀lú yín, màá sì dáàbò bò yín.” w18.09 26 ¶11-12
Saturday, May 23
Ká ní o lè fi mí pa mọ́ sínú Isà Òkú ni, . . . kí o yan àkókò kan sílẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi.—Jóòbù 14:13.
Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan wà tí ìṣòro mu wọ́n lómi débi tí wọ́n fi ronú pé á sàn káwọn kú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìdààmú bá Jóòbù, ó ké jáde pé: ‘Mo kọ ẹ̀mí mi; èmi kì yóò wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin.’ (Jóòbù 7:16) Nígbà tí nǹkan ò rí bí Jónà ṣe rò lẹ́nu iṣẹ́ tí Jèhófà fún un, ìrẹ̀wẹ̀sì bá a, ó wá sọ pé: “Wàyí o, Jèhófà, jọ̀wọ́, gba ọkàn mi kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí, kí n kú sàn ju kí n wà láàyè.” (Jónà 4:3) Bákan náà, ìgbà kan wà tí nǹkan tojú sú wòlíì Èlíjà débi tó fi ronú pé á sàn kóun kú. Ó sọ pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Wàyí o, Jèhófà, gba ọkàn mi kúrò.” (1 Ọba 19:4) Àmọ́ Jèhófà mọyì àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ yìí, kò sì fẹ́ kí wọ́n kú. Dípò tí Jèhófà fi máa bínú torí ohun tí wọ́n sọ, ṣe ló fìfẹ́ gbé wọn ró, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí ẹ̀dùn ọkàn wọn, kí wọ́n sì máa sìn ín nìṣó. w18.09 13 ¶4
Sunday, May 24
Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá.—1 Kọ́r. 3:9.
Àwọn tó ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ máa ń lẹ́mìí aájò àlejò. Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “aájò àlejò” túmọ̀ sí “ṣíṣe inúure sí àwọn tá ò mọ̀ rí.” (Héb. 13:2) Bíbélì mẹ́nu kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ṣe bẹ́ẹ̀ láyé àtijọ́ tá a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. (Jẹ́n. 18:1-5) Ó yẹ káwa náà máa wá ọ̀nà tá a lè gbà ran àwọn míì lọ́wọ́ yálà wọ́n “bá wa tan nínú ìgbàgbọ́” tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (Gál. 6:10) Tá a bá ń fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sáwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, à ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ nìyẹn. (3 Jòh. 5, 8) Nírú àwọn àsìkò bẹ́ẹ̀, a máa ń láǹfààní láti fún ara wa ní “pàṣípààrọ̀ ìṣírí.” (Róòmù 1:11, 12) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àwọn arákùnrin níyànjú pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà, nípa bẹ́ẹ̀, àwọn náà á lè máa bá Jèhófà ṣiṣẹ́. (1 Tím. 3:1, 8, 9; 1 Pét. 5:2, 3) Téèyàn bá ń nàgà fún àǹfààní yìí, ohun tó ń jẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́kàn ni bá ṣe máa ran àwọn míì lọ́wọ́ nípa tara àti nípa tẹ̀mí. (Ìṣe 6:1-4) Àwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn fún àwọn iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì nínú ìjọ gbà pé ayọ̀ wà nínú kéèyàn máa ran àwọn míì lọ́wọ́. w18.08 24 ¶6-7; 25 ¶10
Monday, May 25
Má ṣe fi ọ̀rọ̀ líle bá àgbà ọkùnrin wí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí o pàrọwà fún un bíi bàbá.—1 Tím. 5:1.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tímótì ní ọlá àṣẹ lórí àwọn àgbà ọkùnrin yìí dé ìwọ̀n àyè kan, síbẹ̀ ó gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún wọn, kó sì fìfẹ́ bá wọn lò. Àmọ́ kí la máa ṣe tí ẹnì kan tó dàgbà jù wá lọ bá ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ tàbí tó ń gbé ohun tí Jèhófà kórìíra lárugẹ? Ohun kan ni pé Jèhófà kì í fi ìrísí dáni lẹ́jọ́, ti pé ẹnì kan dàgbà kò túmọ̀ sí pé Jèhófà máa gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́ni náà mọ̀ọ́mọ̀ dá. Ká fi ìlànà tó wà nínú Aísáyà 65:20 sọ́kàn tó sọ pé: “Ní ti ẹlẹ́ṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, a ó pe ibi wá sórí rẹ̀.” Irú ìlànà yìí náà wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí. (Ìsík. 9:5-7) Torí náà, ohun tó yẹ kó máa wà lọ́kàn wa nígbà gbogbo ni bá a ṣe máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé. (Dán. 7:9, 10, 13, 14) Tá a bá ń fi èyí sọ́kàn, a ò ní bẹ̀rù láti fún ẹnikẹ́ni ní ìbáwí tó yẹ láìka ọjọ́ orí rẹ̀ sí.—Gál. 6:1. w18.08 11 ¶13-14
Tuesday, May 26
Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.—Òwe 14:15.
Ó yẹ káwa Kristẹni tòótọ́ mọ bá a ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ yẹ̀ wò dáadáa ká lè dórí ìpinnu tó tọ́. (Òwe 3:21-23; 8:4, 5) Ìdí ni pé, Sátánì àti ayé burúkú yìí lè gbin èrò òdì sí wa lọ́kàn tá ò bá ṣọ́ra. (Éfé. 5:6; Kól. 2:8) Torí náà, ká tó lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání lórí ọ̀rọ̀ kan, ó yẹ ká rí òkodoro òtítọ́ nípa ọ̀rọ̀ náà. Yaágbó-yaájù ìsọfúnni ló wà lónìí. Ṣé ti orí Íńtánẹ́ẹ̀tì la fẹ́ sọ ni àbí ti tẹlifíṣọ̀n àtàwọn ìwé ìròyìn lónírúurú? Kì í ṣèyẹn nìkan, ọ̀pọ̀ ìsọfúnni làwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń fi ránṣẹ́ sí wa lórí fóònù àti kọ̀ǹpútà. Ó yẹ ká kíyè sára gan-an torí pé lónìí, ó wọ́pọ̀ káwọn èèyàn máa fi ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ ránṣẹ́, ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká gbé ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tá a bá gbọ́ yẹ̀ wò dáadáa. w18.08 3 ¶1, 3
Wednesday, May 27
O ti rí ojúure Ọlọ́run.—Lúùkù 1:30.
Nígbà tó tó àkókò lójú Jèhófà láti rán ọmọ rẹ̀ wá sáyé, Jèhófà yan Màríà láti jẹ́ ìyá rẹ̀. Onírẹ̀lẹ̀ ni Màríà, kò sì tíì ní ìbálòpọ̀ rí. Násárétì ló ń gbé, ìyẹn ìlú kan táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kà sí, tó sì jìn sí Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀. (Lúùkù 1:26-33) Ẹni tẹ̀mí ni Màríà, èyí sì hàn nínú ọ̀rọ̀ tó bá Èlísábẹ́tì ìbátan rẹ̀ sọ. (Lúùkù 1:46-55) Èyí fi hàn pé Jèhófà kíyè sí Màríà pé olóòótọ́ ni, ìdí nìyẹn tó fi fún Màríà ní àǹfààní bàǹtà-banta tí ò lérò yìí. Nígbà tí Màríà bí Jésù, Jèhófà ò jẹ́ káwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn tàbí àwọn alákòóso tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn áńgẹ́lì fara han àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ń bójú tó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní pápá nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. (Lúùkù 2:8-14) Àwọn olùṣọ́ àgùntàn yìí ló sì wá kí ọmọ jòjòló náà. (Lúùkù 2:15-17) Ó dájú pé ọ̀nà tí Jèhófà gbà yẹ́ Jésù sí máa ya Màríà àti Jósẹ́fù lẹ́nu gan-an. w18.07 9-10 ¶11-12
Thursday, May 28
Inú bí Jèhófà gan-an sí Sólómọ́nì.—1 Ọba 11:9.
Kí nìdí tí Jèhófà fi bínú sí Sólómọ́nì? Bíbélì sọ pé: “Nítorí ọkàn rẹ̀ ti kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà . . . , ẹni tó fara hàn án lẹ́ẹ̀mejì, tí ó sì kìlọ̀ fún un nípa nǹkan yìí pé kí ó má ṣe tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì. Àmọ́ kò ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ.” Torí náà, Jèhófà pa dà lẹ́yìn Sólómọ́nì, ó sì pàdánù ojúure Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì kú, ìjọba Ísírẹ́lì pín sí méjì, àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ sì kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro. (1 Ọba 11:9-13) Bíi ti Sólómọ́nì, tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí kò ka àwọn ìlànà Jèhófà sí, àjọṣe àwa àti Jèhófà lè bà jẹ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè wà nínú ìjọ àmọ́ kó jẹ́ pé wọn ò ka nǹkan tẹ̀mí sí pàtàkì. Ó sì lè jẹ́ àwọn tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà bí àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ iléèwé wa. Ẹni yòówù kó jẹ́, tí àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ ò bá ka àwọn ìlànà Jèhófà sí, bópẹ́ bóyá wọ́n lè mú ká pàdánù ojúure Jèhófà. w18.07 19 ¶9-10
Friday, May 29
Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.—1 Jòh. 5:19.
Sátánì máa ń lo àwọn fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n láti tan èrò rẹ̀ kálẹ̀. Ó mọ̀ pé àwọn ìtàn aládùn tí wọ́n ń gbé jáde máa ń gbádùn mọ́ni, àmọ́ wọ́n tún máa ń dọ́gbọ́n kọ́ni láti máa ronú kéèyàn sì máa hùwà bíi tàwọn èèyàn ayé. Jésù náà lo ìtàn láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ ìtàn nípa ọkùnrin ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere àti ti ọmọkùnrin kan tó filé sílẹ̀ tó sì ná ogún rẹ̀ ní ìná àpà. (Mát. 13:34; Lúùkù 10:29-37; 15:11-32) Àmọ́, àwọn ìtàn aládùn táwọn èèyàn ayé ń gbé jáde kì í ṣeni láǹfààní, ṣe ni wọ́n máa ń sọ ọkàn ẹni dìbàjẹ́. Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé gbogbo fíìmù tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n ló burú o. Àwọn kan wà tó gbádùn mọ́ni, a sì lè rí nǹkan kọ́ nínú wọn láìsọ ọkàn wa dìbàjẹ́. Síbẹ̀, ó yẹ ká kíyè sára. Torí náà, nígbàkigbà tá a bá ń wo fíìmù tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé wọn ò máa dọ́gbọ́n sọ pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́rùn?’ (Gál. 5:19-21; Éfé. 2:1-3) Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá kíyè sí i pé fíìmù tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n kan ń gbé èrò Sátánì lárugẹ? Ṣe ni kó o sá, bí ìgbà tó ò ń sá fún àrùn tó ń ranni! w19.01 15-16 ¶6-7
Saturday, May 30
Ẹ gba akoto ìgbàlà.—Éfé. 6:17.
Bí àṣíborí ṣe máa ń dáàbò bo ọpọlọ ọmọ ogun kan, bẹ́ẹ̀ náà ni “ìrètí ìgbàlà” tá a ní máa ń dáàbò bo èrò orí wa, ìyẹn bá a ṣe ń ronú. (1 Tẹs. 5:8; Òwe 3:21) Tá ò bá ṣọ́ra, Sátánì lè mú ká ṣí àṣíborí wa. Lọ́nà wo? Ẹ wo ohun tó ṣe fún Jésù. Sátánì mọ̀ dájú pé Jésù ló máa di ọba gbogbo ayé lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ Jésù gbọ́dọ̀ ṣe sùúrù títí di àsìkò tí Jèhófà yàn kalẹ̀. Kí Jésù tó di ọba, ó máa jìyà, á sì kú. Sátánì wá sọ fún un pé ó lè di ọba láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ jẹ gbogbo ìyà yẹn. Sátánì ní tí Jésù bá lè jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ó máa di ọba lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. (Lúùkù 4:5-7) Sátánì ṣì ń lo irú ọgbọ́n yẹn lónìí. Ó mọ̀ pé Jèhófà ti ṣèlérí ọ̀pọ̀ ìbùkún fún wa nínú ayé tuntun. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣe sùúrù kí ìlérí yẹn tó ṣẹ, kódà a tiẹ̀ lè jìyà pàápàá. Torí náà, Sátánì lè mú ká máa ronú pé kò dìgbà tá a bá dúró kí ayé tuntun dé ká tó lè gbádùn ayé wa. Ó fẹ́ ká gbájú mọ́ bá a ṣe máa kó àwọn nǹkan tara jọ, ká sì fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kejì.—Mát. 6:31-33. w18.05 30-31 ¶15-17
Sunday, May 31
Jẹ́ kí ọkàn rẹ máa yọ̀ ní ìgbà ọ̀dọ́ rẹ.—Oníw. 11:9.
Jèhófà fẹ́ kẹ́yin ọ̀dọ́ máa láyọ̀. Torí náà, pọkàn pọ̀ sórí àwọn àfojúsùn tó o ní nínú ìjọsìn Ọlọ́run, sì máa fi Jèhófà sọ́kàn nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, Jèhófà á máa tọ́ ẹ sọ́nà, á máa dáàbò bò ẹ́, á sì máa bù kún ẹ. Máa ronú lórí àwọn ìtọ́ni onífẹ̀ẹ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì máa fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.” (Oníw. 12:1) A gbóríyìn fún ẹ̀yin ọ̀dọ́ wa torí láìka gbogbo ìṣòro tẹ́ ẹ̀ ń kojú sí, ẹ ti pinnu pé Jèhófà lẹ máa fayé yín sìn. Bẹ́ ẹ ṣe ń pinnu àwọn nǹkan tẹ́ ẹ fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà náà lẹ̀ ń fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù. Bákan náà, ẹ ti pinnu pé ẹ ò ní jẹ́ kí ohunkóhun nínú ayé yìí pín ọkàn yín níyà. Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé gbogbo ìsapá yín ò ní já sásán. A sì fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé gbogbo wa la nífẹ̀ẹ́ yín, àá sì máa tì yín lẹ́yìn. Paríparí ẹ̀, torí pé ẹ̀ ń fayé yín sin Jèhófà, ìgbésí ayé yín máa ládùn, á sì lóyin. w18.04 29 ¶17, 19