June
Monday, June 1
Tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, ó máa fún yín.—Jòh. 15:16.
Ó dájú pé ìlérí yìí máa fáwọn àpọ́sítélì lókun gan-an! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì yé wọn nígbà yẹn pé Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wọn máa tó kú, síbẹ̀ Jèhófà ò ní fi wọ́n sílẹ̀. Jèhófà ṣe tán láti dáhùn àdúrà wọn, kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ. Kò sì pẹ́ rárá táwọn fúnra wọn fi rí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà tí wọ́n gbà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. (Ìṣe 4:29, 31) Bọ́rọ̀ ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Tá ò bá dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àá máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù nìṣó. Yàtọ̀ síyẹn, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa, á sì ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìṣòro èyíkéyìí tá a bá kojú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Fílí. 4:13) A mà dúpẹ́ o, pé a láǹfààní láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù àti pé Jèhófà ń dáhùn àdúrà wa! Àwọn ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa yìí ló ń fún wa lókun ká lè máa so èso.—Ják. 1:17. w18.05 21 ¶17-18
Tuesday, June 2
Ẹ sì jẹ́ ká gba . . . ara wa níyànjú, ní pàtàkì jù lọ bí ẹ ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.—Héb. 10:24, 25.
Láàárín nǹkan bí ọdún márùn-ún, àwọn Kristẹni tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù kíyè sí i pé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ti dé tán sórí Jerúsálẹ́mù àti pé ó ti tó àkókò tó yẹ káwọn fi ibẹ̀ sílẹ̀ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Ìṣe 2:19, 20; Lúùkù 21:20-22) Nígbà tó sì máa di ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Róòmù mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ sórí ìlú náà, wọ́n sì pa á run. Bíi tàwọn Júù ìgbà yẹn lásìkò tiwa yìí náà rí. Ìdí sì ni pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé, ó “tóbi, ó sì jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù gan-an.” (Jóẹ́lì 2:11) Wòlíì Sefanáyà sọ pé: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Sef. 1:14) Ohun tí wòlíì yẹn sọ kan àwa náà lónìí. Torí àwa náà ti mọ̀ pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé, ó yẹ ká fọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé “kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Héb. 10:24) Torí náà, ó yẹ ká túbọ̀ jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn ará wa máa jẹ wá lógún, ká sì máa fún wọn níṣìírí nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀. w18.04 20 ¶1-2
Wednesday, June 3
Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, má sì jáyà, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí o bá lọ.—Jóṣ. 1:9.
Ẹ wo bí ìyẹn ti máa fọkàn Jóṣúà balẹ̀ tó bó ṣe ń múra láti kó àwọn èèyàn Jèhófà wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Bí Jèhófà ṣe ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ níṣìírí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ ló ń fún wọn lápapọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà mọ̀ pé àwọn Júù máa nílò ìṣírí nígbà tí wọ́n wà nígbèkùn Bábílónì, torí náà ó sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú yìí fún wọn nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan, ó ní: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.” (Aísá. 41:10) Nígbà tó yá, Jèhófà fún àwọn Kristẹni ìgbàanì níṣìírí, bó sì ṣe ń fún àwa náà nìyẹn. (2 Kọ́r. 1:3, 4) Jésù náà rí ìṣírí gbà lọ́dọ̀ Baba rẹ̀. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó gbọ́ tí ohùn kan jáde wá láti ọ̀run pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mát. 3:17) Ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún Jésù lókun jálẹ̀ àkókò tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé! w18.04 16 ¶3-5
Thursday, June 4
O ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú.—Jẹ́n. 2:17.
Àwọn kan ronú pé àṣẹ tí Jèhófà pa fún Ádámù kò fún un ní òmìnira láti ṣe ohun tó fẹ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò mọ̀ pé ìyàtọ̀ wà láàárín kéèyàn lómìnira àti kéèyàn pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Ádámù àti Éfà ní òmìnira láti pinnu bóyá wọ́n á ṣègbọràn sí Ọlọ́run àbí wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, “igi ìmọ̀ rere àti búburú” tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì sì jẹ́ kíyẹn ṣe kedere sí Ádámù àti Éfà. (Jẹ́n. 2:9) Àmọ́, àṣẹ tí Jèhófà pa fún Ádámù àti Éfà jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n lo òmìnira wọn. Àmọ́ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ pinnu láti ṣàìgbọràn. Ṣé ìpinnu tí wọ́n ṣe yìí mú kí wọ́n túbọ̀ ní òmìnira? Rárá. Torí pé wọ́n kọ Jèhófà sílẹ̀, tí wọ́n sì yàn láti ṣe tinú wọn, wọ́n pàdánù òmìnira tòótọ́ tí Jèhófà fún wọn. w18.04 5-6 ¶9-12
Friday, June 5
Nínú gbogbo ìdààmú wọn, ìdààmú bá òun náà.—Àìsá. 63:9.
Kì í ṣe pé àánú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń ṣe é nìkan ni, ó tún máa ń gbé ìgbésẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jìyà ní Íjíbítì, Jèhófà mọ bí ìyà tí wọ́n ń jẹ ṣe rí lára wọn débi pé ó gbé ìgbésẹ̀ láti dá wọn sílẹ̀. Ó sọ fún Mósè pé: “Mo ti rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn mi . . . , mo sì ti gbọ́ igbe wọn . . . mo mọ̀ dáadáa pé wọ́n ń jẹ̀rora. Màá lọ gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì.” (Ẹ́kís. 3:7, 8) Àánú tí Jèhófà ní ló mú kó dá àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ lóko ẹrú. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àìmọye ìgbà làwọn ọ̀tá gbéjà kò wọ́n. Kí ni Jèhófà wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ṣàánú wọn torí pé àwọn tó ń ni wọ́n lára àtàwọn tó ń fìyà jẹ wọ́n mú kí wọ́n máa kérora.” Torí pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn èèyàn rẹ̀, ó ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì lo àwọn onídàájọ́ láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.—Oníd. 2:16, 18. w19.03 15 ¶4-5
Saturday, June 6
Ṣé obìnrin lè gbàgbé ọmọ rẹ̀ tó ṣì ń mu ọmú tàbí kó má ṣàánú ọmọ tó lóyún rẹ̀? Tí àwọn obìnrin yìí bá tiẹ̀ gbàgbé, mi ò jẹ́ gbàgbé rẹ láé.—Àìsá. 49:15.
Òfin méjì àkọ́kọ́ nínú Òfin Mẹ́wàá sọ pé Jèhófà nìkan làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn, ó sì kìlọ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ bọ̀rìṣà. (Ẹ́kís. 20:3-6) Kì í ṣe Jèhófà ni òfin yẹn ṣe láǹfààní, kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ló máa jàǹfààní tí wọ́n bá pa òfin náà mọ́. Tí wọ́n bá bọ̀rìṣà, nǹkan máa ń burú fún wọn. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jèhófà máa ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n bá pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọ́n sì ń ṣèdájọ́ òdodo. (1 Ọba 10:4-9) A ò lè dá Jèhófà lẹ́bi tí àwọn tó wà nípò àṣẹ bá ń tẹ òfin lójú, tí wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn ọmọ abẹ́ wọn. Àmọ́ o, Jèhófà ń kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, kò fọ̀rọ̀ wa ṣeré, ó sì mọ̀ ọ́n lára tá a bá ń jìyà. Ọ̀rọ̀ wa jẹ Jèhófà lọ́kàn gan-an, kódà ó ju ti abiyamọ kan tó tatí were nígbà tó gbọ́ ẹkún ọmọ rẹ̀. Ó lè má dá sọ́rọ̀ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àmọ́ bópẹ́ bóyá, á dá sí i, gbogbo àwọn ẹni ibi tí kò ronú pìwà dà ló sì máa jẹ iyán wọn níṣu. w19.02 22 ¶13-15
Sunday, June 7
Ìfẹ́ rẹ ni kó ṣẹ, kì í ṣe tèmi. —Lúùkù 22:42.
Láwọn ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, àwọn ìpàdé wa máa ń dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ lára Jésù àti bó ṣe rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ tó sì fẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Ìyẹn máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, ká sì máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn. Tá a bá ronú nípa bí Jésù ṣe lo ìgboyà láwọn ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀. Ó mọ̀ pé láìpẹ́ àwọn ọ̀tá máa fi òun ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n máa lu òun, wọ́n á sì pa òun. (Mát. 20:17-19) Síbẹ̀, kò fà sẹ́yìn, ó gbà kí wọ́n pa òun. Nígbà tí àsìkò tó, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ tí wọ́n jọ wà ní Gẹtisémánì pé: “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a lọ. Wò ó! Afinihàn mi ti sún mọ́ tòsí.” (Mát. 26:36, 46) Nígbà táwọn jàǹdùkú náà dé, ṣe ni Jésù bọ́ síwájú, ó sọ fún wọn pé òun lẹni tí wọ́n ń wá, ó sì ní kí wọ́n jẹ́ káwọn àpọ́sítélì òun máa lọ. (Jòh. 18:3-8) Àbí ẹ ò rí i pé Jésù nígboyà! Bíi ti Jésù, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn náà ń lo ìgboyà. w19.01 27-28 ¶7-8
Monday, June 8
Ẹ wá ìwà pẹ̀lẹ́.—Sef. 2:3.
Bí ayàwòrán kan ṣe máa ń lo onírúurú àwọ̀ láti kun àwòrán kan kó bàa lè gbé ẹwà rẹ̀ yọ, bẹ́ẹ̀ náà la gbọ́dọ̀ ní àwọn ànímọ́ pàtàkì kan kó tó lè hàn pé a jẹ́ ọlọ́kàn tútù. Lára àwọn ànímọ́ náà ni, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ìtẹríba tàbí ìgbọràn, ìwà tútù àti ìgboyà. Àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nìkan ló máa ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Lára ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé ká jẹ́ onínú tútù. (Mát. 5:5; Gál. 5:23) Inú Sátánì kì í dùn rárá pé à ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Torí náà, tá a bá tiẹ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tá a sì jẹ́ onínú tútù, àwọn èèyàn inú ayé Sátánì ṣì máa kórìíra wa. (Jòh. 15:18, 19) Ìdí nìyẹn tá a fi nílò ìgboyà ká lè kojú Sátánì. Àwọn tí kò bá lọ́kàn tútù máa ń gbéra ga, wọ́n máa ń bínú lódìlódì, wọn kì í sì í ṣègbọràn sí Jèhófà. Irú ẹni tí Sátánì jẹ́ gan-an nìyẹn, abájọ tó fi kórìíra àwọn ọlọ́kàn tútù. Ti pé ẹ̀dá èèyàn lè ní ọkàn tútù fi hàn pé ẹni burúkú ni Sátánì àti pé òpùrọ́ ni. Kí nìdí? Ìdí ni pé láìka ohun tí Sátánì ń sọ àtohun tó ń ṣe sí, àwọn ọlọ́kàn tútù kì í fi Jèhófà sílẹ̀!—Jóòbù 2:3-5. w19.02 8-9 ¶3-5
Tuesday, June 9
Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ.—Àìsá. 41:10.
Jèhófà mọ̀ pé ohun kan máa ṣẹlẹ̀ táá mú kẹ́rù ba àwọn tó ń gbé ní Bábílónì. Àwọn ọmọ ogun Mídíà àti Páṣíà máa gbógun ja ìlú Bábílónì, Jèhófà sì máa lo àwọn ọmọ ogun yìí láti dá àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀. (Aísá. 41:2-4) Nígbà táwọn ará Bábílónì àtàwọn orílẹ̀-èdè míì rí i pé àwọn ọ̀tá ti ń kógun bọ̀, wọ́n ń fi ara wọn lọ́kàn balẹ̀, wọ́n sì ń sọ fún ara wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ alágbára.’ Wọ́n tún ṣe kún àwọn òrìṣà wọn torí wọ́n rò pé àwọn òrìṣà yẹn á dáàbò bò wọ́n. (Aísá. 41:5-7) Àmọ́, Jèhófà fi àwọn Júù tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀ pé: ‘Ìwọ Ísírẹ́lì [kì í ṣe àwọn aládùúgbò yín] ni ìránṣẹ́ mi. Má wò yí ká tàbí ṣàníyàn, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.’ (Aísá. 41:8-10) Ẹ kíyè sí i pé Jèhófà sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run rẹ.” Ohun tí Jèhófà sọ yìí jẹ́ kó dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lójú pé òun ò gbàgbé wọn àti pé àwọn náà ṣì jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ó tún sọ fún wọn pé òun máa dáàbò bò wọ́n, òun sì máa “pèsè àsálà” fún wọn. Kò sí àní-àní pé àwọn ọ̀rọ̀ yẹn jẹ́ kọ́kàn àwọn Júù náà balẹ̀.—Aísá. 46:3, 4. w19.01 4 ¶8
Wednesday, June 10
Ohùn kan sì dún láti ọ̀run pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, àyànfẹ́; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”—Máàkù 1:11.
Máàkù 1:9-11 ròyìn ìgbà àkọ́kọ́ tí Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run. Jèhófà sọ pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, àyànfẹ́; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.” Ẹ wo bí inú Jésù ti máa dùn tó nígbà tó gbọ́ bí Baba rẹ̀ ṣe fi í lọ́kàn balẹ̀, tó sì fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀! Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tó ṣe pàtàkì nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Jésù. Àkọ́kọ́, Ọmọ òun ni Jésù. Ìkejì, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Ẹ̀kẹta sì ni pé Jèhófà ti tẹ́wọ́ gbà á. Bí Jèhófà ṣe sọ pé “Ìwọ ni Ọmọ mi” fi hàn pé Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ àjọṣe tuntun pẹ̀lú Baba rẹ̀ ọ̀run. Kò sí àní-àní pé ọmọ Ọlọ́run ni Jésù nígbà tó wà lọ́run. Àmọ́ nígbà tó ṣèrìbọmi, Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án. Ọlọ́run tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Ọmọ tí òun fi ẹ̀mí yàn ni Jésù, èyí sì fi hàn pé Jésù nírètí láti pa dà sí ọ̀run kó sì di Ọba àti Àlùfáà Àgbà tí Ọlọ́run yàn. (Lúùkù 1:31-33; Héb. 1:8, 9; 2:17) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe sọ nígbà ìrìbọmi Jésù pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi.”—Lúùkù 3:22. w19.03 8 ¶3-4
Thursday, June 11
Kò sí ọgbọ́n . . . tó lòdì sí Jèhófà tó lè dúró.—Òwe 21:30.
Ọjọ́ pẹ́ tọ́mọ aráyé ti ń gbàmọ̀ràn tí kò ṣàǹfààní. Sátánì lẹni àkọ́kọ́ tó gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn burúkú, ó sọ fún Ádámù àti Éfà pé wọ́n á túbọ̀ láyọ̀ tí wọ́n bá fúnra wọn pinnu ohun tí wọ́n fẹ́. (Jẹ́n. 3:1-6) Ẹ gbọ́ ná, ta ló yàn án ní agbani-nímọ̀ràn? Ìwà ọ̀yájú nìyẹn, ìkọjá-àyè sì ni pẹ̀lú. Kì í ṣe pé Sátánì nífẹ̀ẹ́ tọkọtaya yẹn, kàkà bẹ́ẹ̀ bó ṣe máa fi wọ́n sábẹ́ ara rẹ̀ ló ń wá. Ó fẹ́ kí Ádámù àti Éfà, títí kan àwọn àtọmọdọ́mọ wọn máa jọ́sìn òun dípò Jèhófà. Jèhófà ló fún tọkọtaya yẹn ní gbogbo ohun tí wọ́n ní, òun ló so wọ́n pọ̀, òun ló fi ọgbà Édẹ́nì jíǹkí wọn, ó dá wọn pẹ̀lú ara tí kò lábùkù, wọ́n á sì lè wà láàyè títí láé. Ó bani nínú jẹ́ pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara wọn di àjèjì sí i. Bẹ́yin náà ṣe mọ̀, àbájáde rẹ̀ burú gan-an. Ṣe lọ̀rọ̀ wọn dà bí òdòdó téèyàn já kúrò lára igi òdòdó, díẹ̀díẹ̀, á rọ, á sì gbẹ dànù. Kì í ṣe àwọn nìkan ló jìyà àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àwọn àtọmọdọ́mọ wọn náà jẹ ńbẹ̀. (Róòmù 5:12) Síbẹ̀, èyí tó pọ̀ jù nínú ọmọ aráyé ló kọ̀ láti fara wọn sábẹ́ Ọlọ́run, torí pé tinú wọn ni wọ́n ń ṣe. (Éfé. 2:1-3) Àbájáde ìpinnu wọn fi hàn pé òótọ́ ni ohun tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. w18.12 20 ¶3-4
Friday, June 12
Àwọn nǹkan yìí ni àwa náà ń sọ, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi kọ́ni nípa ọgbọ́n èèyàn, bí kò ṣe pẹ̀lú àwọn tí a fi kọ́ni nípasẹ̀ ẹ̀mí, bí a ṣe ń fi àwọn ọ̀rọ̀ tẹ̀mí ṣàlàyé àwọn nǹkan tẹ̀mí.—1 Kọ́r. 2:13.
Ọ̀mọ̀wé ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó kéré tán ó gbọ́ èdè méjì. (Ìṣe 5:34; 21:37, 39; 22:2, 3) Síbẹ̀, tó bá kan ọ̀rọ̀ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, Pọ́ọ̀lù ò fàyè gba èrò ayé rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlànà Ìwé Mímọ́ ló máa ń gbé èrò rẹ̀ kà. (Ìṣe 17:2; 1 Kọ́r. 2:6, 7) Ìyẹn jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gan-an, ó sì tún fojú sọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun. (2 Tím. 4:8) Ó dájú pé èrò Jèhófà ga ju tayé lọ fíìfíì. Tá a bá ń jẹ́ kí èrò rẹ̀ máa darí wa, a máa láyọ̀, ayé wa á sì nítumọ̀. Àmọ́ Jèhófà ò ní fipá mú wa pé ká fara mọ́ èrò rẹ̀. Bákan náà, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kì í fipá mú wa ṣe nǹkan, àwọn alàgbà náà ò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 24:45; 2 Kọ́r. 1:24) Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa sapá láti mú kí èrò rẹ̀ bá ti Jèhófà mu. w18.11 20-21 ¶12-13
Saturday, June 13
Ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ kò ní sí mọ́.—Àìsá. 35:10.
Ọlọ́run ṣèlérí nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà pé lẹ́yìn táwọn èèyàn Jèhófà bá pa dà sí ilẹ̀ wọn, kò ní sóhun táá pọ́n wọn lójú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní máa bẹ̀rù àwọn ẹranko ẹhànnà àtàwọn èèyànkéèyàn. Tọmọdétàgbà ni ọkàn wọn máa balẹ̀. Ǹjẹ́ ìlérí yẹn ò rán wa létí bí nǹkan ṣe rí nínú ọgbà Édẹ́nì? (Aísá. 11:6-9; 35:5-10; 51:3) Àmọ́ ẹ kíyè sí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ pé gbogbo ilẹ̀ ayé ló máa kún fún “ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun” kì í ṣe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nìkan. Aísáyà tún tẹnu mọ́ ọn pé àwọn ẹranko ẹhànnà àtàwọn èèyànkéèyàn kò ní da àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti ìgbèkùn dé láàmú. Bákan náà, ilẹ̀ wọn máa so èso wọ̀ǹtìwọnti, torí pé àwọn igi á máa rómi tó pọ̀ fà mu bó ṣe rí nínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́n. 2:10-14; Jer. 31:12) Àmọ́, ṣé ìyẹn nìkan ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn? Rárá o. Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn tó ti ìgbèkùn dé rí ìwòsàn gbà lọ́nà ìyanu. Bí àpẹẹrẹ, kò sí ẹ̀rí pé ojú àwọn afọ́jú là. Torí náà, ó ṣe kedere pé lọ́jọ́ iwájú Ọlọ́run ṣì máa wo àwọn èèyàn sàn bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn. w18.12 5 ¶11-12
Sunday, June 14
[Ẹ máa] rìn nínú òtítọ́.—3 Jòh. 3.
Kì í ṣe ọjọ́ kan péré la fẹ́ fi rìn nínú òtítọ́, títí láé la ó máa rìn nínú rẹ̀. Àmọ́ kí lá jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé àá máa bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́? Máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ kó o sì máa ronú lé ohun tó o kà. Bó o ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ máa jẹ́ kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ. Ìyẹn á mú kó o túbọ̀ mọyì òtítọ́ kó o sì pinnu pé o ò ní fi í sílẹ̀ láé. Yàtọ̀ síyẹn, Òwe 23:23 tún gbà wá níyànjú pé ká ra “ọgbọ́n àti ìbáwí àti òye.” Ìmọ̀ Bíbélì tá a ní nìkan ò tó, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí òtítọ́ Bíbélì tá a mọ̀ máa darí ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́. Òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a bá ní máa jẹ́ ká rí bí gbogbo Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣe máa ṣe wá láǹfààní. Ọgbọ́n ló máa jẹ́ ká fi gbogbo ohun tá à ń kọ́ sílò. Nígbà míì sì rèé, òtítọ́ máa ń bá wa wí ní ti pé ó máa ń jẹ́ ká rí àwọn ibi tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe. Á dáa ká tètè máa ṣe àwọn àtúnṣe yìí torí Bíbélì sọ pé ìbáwí ṣeyebíye ju fàdákà lọ.—Òwe 8:10. w18.11 9 ¶3; 11 ¶13-14
Monday, June 15
Ra òtítọ́, má sì tà á láé. —Òwe 23:23.
Kí lohun tá a ní tó ṣeyebíye jù lọ sí wa? Ṣé wàá fẹ́ fi ohun míì tí kò níye lórí rọ́pò rẹ̀? Kò ṣòro fáwa tá à ń sin Jèhófà láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Ìdí ni pé àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà lohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa, a ò sì lè yááfì ẹ̀ fún ohunkóhun láé. Yàtọ̀ síyẹn, a mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì torí pé òun ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Baba wa ọ̀run. (Kól. 1:9, 10) Jèhófà ni Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá, ó sì ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ti jẹ́ ká mọ ohun tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí àtàwọn ànímọ́ àtàtà tó ní. Bákan náà, ó jẹ́ ká mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an débi pé ó fi Jésù Ọmọ rẹ̀ rà wá pa dà. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ nípa Ìjọba Mèsáyà tó ń bọ̀ àti nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Jèhófà tún lo Bíbélì láti kọ́ wa láwọn ìwà tó yẹ ká máa hù. A mọyì àwọn òtítọ́ yìí torí wọ́n ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa, èyí sì ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀. w18.11 3 ¶1-2
Tuesday, June 16
Ẹ má ṣe máa parọ́ fún ara yín.—Kól. 3:9.
Kò sóhun tó bò lójú Jèhófà torí pé “ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu” ní ojú rẹ̀. (Héb. 4:13) Bí àpẹẹrẹ, Ananíà àti Sáfírà gbìmọ̀ pọ̀ láti tan àwọn àpọ́sítélì jẹ. Wọ́n ta ohun ìní wọn, wọ́n sì kó apá kan lára owó náà wá fáwọn àpọ́sítélì. Ananíà àti Sáfírà fẹ́ káwọn ará ìjọ máa fojú pàtàkì wò wọ́n, wọ́n wá parọ́ pé gbogbo owó tí wọ́n ta ohun ìní wọn làwọn kó wá pátápátá. Síbẹ̀, Jèhófà rí ohun tí wọ́n ṣe, ó sì fìyà tó tọ́ jẹ wọ́n. (Ìṣe 5:1-10) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó bá ń parọ́? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì àti gbogbo àwọn òpùrọ́ tí kò bá ronú pìwà dà ni Jèhófà máa fi sọ̀kò sínú “adágún iná.” (Ìṣí. 20:10; 21:8; Sm. 5:6) A mọ̀ pé Jèhófà “kì í ṣe ènìyàn tí yóò fi purọ́.” Kódà, Bíbélì fi dá wa lójú pé, “kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.” (Nọ́ń. 23:19; Héb. 6:18) “Jèhófà kórìíra . . . ahọ́n èké.” (Òwe 6:16, 17) Ká tó lè rí ojú rere rẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo. w18.10 8 ¶10-13
Wednesday, June 17
Máa ronú lórí àwọn nǹkan yìí.—1 Tím. 4:15.
Ká sọ pé ẹni tó gbà ẹ́ síṣẹ́ sọ pé kó o dáwó fún ayẹyẹ kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn èké, kí ni wàá ṣe? Dípò tí wàá fi dúró kí irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ kó o tó ronú nípa ohun tí wàá ṣe, á dáa kó o ti ronú nísinsìnyí nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe nírú ipò bẹ́ẹ̀. Tí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ bá wá ṣẹlẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti ṣe ohun tó tọ́. Tá a bá ti ronú ohun tá a máa ṣe kí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì nípa ìlera tó ṣẹlẹ̀, àá lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Lóòótọ́, a ti pinnu pé a ò ní gba ẹ̀jẹ̀ tàbí èyíkéyìí lára àwọn èròjà mẹ́rin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀. Síbẹ̀, àwọn ìtọ́jú kan wà tó la ẹ̀jẹ̀ lọ tó máa gba pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe ìpinnu tó bá ìlànà Bíbélì mu. (Ìṣe 15:28, 29) Kò ní dáa kó jẹ́ pé ìgbà tá a bá wà nílé ìwòsàn, tá à ń jẹ̀rora, táwọn dókítà sì ń fúngun mọ́ wa láti ṣèpinnu làá ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ronú ohun tá a máa ṣe. Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká ti ṣèwádìí, ká kọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù nípa irú ìtọ́jú tá a fẹ́, ká sì bá dókítà wa sọ̀rọ̀. w18.11 24 ¶5; 26 ¶15-16
Thursday, June 18
Ẹni tó ń fetí sí mi á máa gbé lábẹ́ ààbò.—Òwe 1:33.
Olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó sì máa ń fìfẹ́ bójú tó àwọn tó jẹ́ tirẹ̀. Ìyẹn máa ń mú kó pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. Àwọn ohun tá a mọ̀ yìí fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé mìmì kan ò lè mì wá bá a ṣe ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Èyí mú kó dá wa lójú pé Jèhófà á dáàbò bò wá bí ìpọ́njú ńlá ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé. (Ìṣí. 7:9, 10) Torí náà, gbogbo àwa èèyàn Jèhófà lọ́mọdé lágbà, yálà ẹni tára ẹ̀ le tàbí aláàbọ̀ ara, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà máa dáàbò bò wá nígbà ìpọ́njú ńlá. Dípò ká máa bẹ̀rù ohun táá ṣẹlẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá, ṣe ni inú wa á máa dùn! Àá máa rántí ọ̀rọ̀ ti Jésù sọ, pé: “Ẹ gbé ara yín nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:28) Kódà, nígbà tí Gọ́ọ̀gù ìyẹn àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tó lágbára gan-an bá gbéjà kò wá, ọkàn wa á balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. (Ìsík. 38:2, 14-16) Kí ló máa jẹ́ kọ́kàn àwa èèyàn Ọlọ́run balẹ̀? Ọkàn wa máa balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà kò ní yí pa dà. Á wà pẹ̀lú wa, á gba tiwa rò, á sì gbà wá là.—Aísá. 26:20. w18.09 26 ¶15-16
Friday, June 19
O ti wá ṣeyebíye ní ojú mi, . . . mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.—Àìsá. 43:4.
Ó dájú pé ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ máa balẹ̀ nígbà tí Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí fún wọn. Jẹ́ kó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ, kò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí fáwọn tó ń fòótọ́ inú sin Jèhófà pé: “Bí Ẹni tí ó ní agbára ńlá, òun yóò gbà là. Òun yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí rẹ pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀.” (Sef. 3:16, 17) Jèhófà ṣèlérí pé òun máa dúró ti àwọn ìránṣẹ́ òun láìka ìṣòro yòówù tí wọ́n bá ń kojú sí. Bíbélì sọ pé: “Ìhà ni a óò gbé yín sí, orí eékún sì ni a ó ti máa ṣìkẹ́ yín. Bí ènìyàn tí ìyá rẹ̀ ń tù nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi fúnra mi yóò ṣe máa tù yín nínú.” (Aísá. 66:12, 13) Ẹ fojú inú wo bó ṣe máa rí lára ọmọ kan tí ìyá rẹ̀ gbé sórí itan, tó ń ṣìkẹ́, tó sì ń pasẹ̀ fún! Jèhófà lo àfiwé yẹn ká lè mọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ tó. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà, ó mọyì rẹ, títí láé lá sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ.—Jer. 31:3. w18.09 13 ¶6-7
Saturday, June 20
Ta ló fẹ́ mú ẹ̀bùn wá fún Jèhófà lónìí?—1 Kíró. 29:5.
Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn máa ń yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ Jèhófà. (Ẹ́kís. 36:2; Neh. 11:2) Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló wà tá a lè yọ̀ǹda ara wa fún. A lè yọ̀ǹda àkókò wa àtàwọn nǹkan tá a ní, kódà a lè fi àwọn iṣẹ́ tá a mọ̀ ọ́n ṣe ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀, Jèhófà sì máa bù kún ẹ lọ́pọ̀ yanturu. Àwọn tó bá yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run máa ń ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Margie. Ọdún méjìdínlógún (18) ló fi bá àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣiṣẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́bìnrin ló ti ràn lọ́wọ́, tó sì ti dá lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Arábìnrin Margie gbà pé iṣẹ́ yìí ti fún òun láǹfààní láti fún àwọn ará níṣìírí kóun náà sì rí ìṣírí gbà. (Róòmù 1:12) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó kojú ìṣòro, àwọn ọ̀rẹ́ tó ní lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé ló fún un níṣìírí. Ǹjẹ́ ìwọ náà ti fìgbà kan rí yọ̀ǹda ara rẹ fún irú iṣẹ́ ìkọ́lé bẹ́ẹ̀? w18.08 25 ¶9, 11
Sunday, June 21
Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fojú ọmọdé wò ọ́ rárá. Àmọ́, kí o jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn olóòótọ́ nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.—1 Tím. 4:12.
Ó ṣeé ṣe kí Tímótì ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lẹ́ni ọgbọ̀n [30] ọdún nígbà tí Pọ́ọ̀lù gbà á nímọ̀ràn yìí. Síbẹ̀, iṣẹ́ ńlá ni Pọ́ọ̀lù ní kó máa bójú tó nínú ìjọ. Kókó tó wà nínú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí ṣe kedere. A ò gbọ́dọ̀ fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀dọ́kùnrin torí pé wọ́n kéré lọ́jọ́ orí. Ó ṣe tán, ẹni ọgbọ̀n [30] ọdún ó lé díẹ̀ ni Jésù nígbà tó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ní àwọn ilẹ̀ kan, wọ́n máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀dọ́kùnrin. Àwọn alàgbà tó wá láti irú ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè má fẹ́ dámọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́kùnrin láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. Àmọ́ gbogbo àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé Ìwé Mímọ́ ò sọ ọjọ́ orí tẹ́nì kan gbọ́dọ̀ jẹ́ kó tó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà.—1 Tím. 3:1-10, 12, 13; Títù 1:5-9. w18.08 11-12 ¶15-16
Monday, June 22
Yẹra fún . . . àwọn ohun tí wọ́n ń fi ẹ̀tàn pè ní “ìmọ̀.”— 1 Tím. 6:20.
Ká tó lè ṣèpinnu tó dáa nípa ọ̀rọ̀ kan, a gbọ́dọ̀ ní ìsọfúnni tó péye nípa ọ̀rọ̀ náà. Torí náà, ó yẹ ká fọgbọ́n yan irú àwọn ìsọfúnni tá a máa yẹ̀ wò àtàwọn ìròyìn tá a máa kà. (Fílí. 4:8, 9) Kò yẹ ká máa fàkókò wa ṣòfò lórí àwọn ìkànnì tó ń gbé ìròyìn èké jáde, kò sì yẹ ká máa ka àwọn ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ táwọn èèyàn fi ń ránṣẹ́ kiri. Ní pàtàkì jù lọ, a gbọ́dọ̀ yẹra fáwọn ìkànnì táwọn apẹ̀yìndà fi ń tan irọ́ kálẹ̀. Ohun táwọn apẹ̀yìndà yìí ń wá ni bí wọ́n á ṣe tú wa ká, tí wọ́n á sì bomi la òtítọ́ tá a mọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, kò yẹ ká fojú kéré àkóbá tí ìsọfúnni tí kò péye lè ṣe fún wa. Lára ẹ̀ ni pé ó lè ṣì wá lọ́nà, kó sì mú ká ṣèpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Mósè. Mẹ́wàá nínú àwọn méjìlá tó lọ ṣe amí Ilẹ̀ Ìlérí ló mú ìròyìn tí kò dáa wálé. (Núm. 13:25-33) Àwọn ìròyìn tó ń mọ́kàn ẹni pami tó sì kún fún àbùmọ́ tó fa kíki ni wọ́n ń sọ, èyí wá mú kí àyà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í já. (Núm. 14:1-4, 6-10) Dípò káwọn èèyàn náà wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ṣe ni wọ́n gba ìròyìn burúkú náà gbọ́. w18.08 4 ¶4-5
Tuesday, June 23
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́.—1 Kọ́r. 15:33.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló láwọn ànímọ́ kan tó dáa, kódà ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni kì í hùwàkiwà. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé o lè máa bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kẹ́gbẹ́? Ó yẹ kó o ronú lórí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà tó o bá ń bá wọn rìn. Ṣé wọ́n lè mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Kí ló máa ń jẹ wọ́n lọ́kàn? Bí àpẹẹrẹ, ṣé kì í ṣọ̀rọ̀ aṣọ, owó, àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, bí wọ́n á ṣe gbafẹ́ àti bí wọ́n á ṣe kó nǹkan tara jọ ni wọ́n máa ń sọ ní gbogbo ìgbà? Ṣé wọ́n sábà máa ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa àwọn míì, kí wọ́n sì máa sọ̀rọ̀ rírùn? Jésù kìlọ̀ pé: “Lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ.” (Mát. 12:34) Tó o bá rí i pé àwọn tó ò ń bá rìn lè ba àjọṣe ìwọ àti Jèhófà jẹ́, ó yẹ kó o gbé ìgbésẹ̀ kíá, kó o dín wọléwọ̀de rẹ pẹ̀lú wọn kù tàbí kó o tiẹ̀ yẹra fún wọn pátápátá.—Òwe 13:20. w18.07 19 ¶11
Wednesday, June 24
Mósè, ló jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́ jù lọ nínú gbogbo èèyàn.—Nọ́ń. 12:3.
Nígbà tí Mósè pé ẹni ọgọ́rin (80) ọdún, Jèhófà sọ fún un pé òun ló máa gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lóko ẹrú ní Íjíbítì. (Ẹ́kís. 3:10) Jèhófà mú sùúrù fún un, kódà ó tún fún Mósè lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu. (Ẹ́kís. 4:2-9, 21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè fagbára mú Mósè kó lè ṣègbọràn láìjanpata. Àmọ́, Jèhófà ò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló mú sùúrù fún Mósè, ó sì fi ìránṣẹ́ rẹ̀ onírẹ̀lẹ̀ yìí lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa wà pẹ̀lú rẹ̀. Ṣé ọ̀nà tí Jèhófà lò yìí gbéṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé Mósè di aṣáájú tó ta yọ, ó sì máa ń gba tàwọn míì rò gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe gba tiẹ̀ náà rò. Tó o bá ní ọlá àṣẹ déwọ̀n àyè kan lórí àwọn míì, ó ṣe pàtàkì kó o fara wé Jèhófà, kó o máa gba tiwọn rò, kó o sì máa ṣe sùúrù pẹ̀lú wọn. (Kól. 3:19-21; 1 Pét. 5:1-3) Tó o bá ń sapá láti fara wé Jèhófà àti Jésù tó jẹ́ Mósè Títóbi Jù, wàá jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, ara sì máa tu àwọn míì nígbà tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ rẹ.—Mát. 11:28, 29. w18.09 24-25 ¶7-10
Thursday, June 25
Ó mà dára o, ó mà dùn o pé kí àwọn ará máa gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan!—Sm. 133:1.
Pinnu pé wàá máa gbé àwọn míì ró, wàá sì máa ṣe ipa tìrẹ kí ìṣọ̀kan lè gbilẹ̀ láàárín àwọn ará. A gbóríyìn fún ẹ tó o bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ǹjẹ́ o lè “gbòòrò síwájú,” ìyẹn ni pé, kó o túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará ìjọ yín? (2 Kọ́r. 6:11-13) Ǹjẹ́ o lè fi kún ìsapá rẹ ládùúgbò tó ò ń gbé kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ lè túbọ̀ máa tàn? Táwọn aládùúgbò wa bá kíyè sí i pé a kì í sọ̀rọ̀kọ́rọ̀, a sì máa ń hùwà ọmọlúàbí, ìyẹn lè mú kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Torí náà, bi ara rẹ pé: ‘Ojú wo làwọn ará àdúgbò fi ń wò mí? Ṣé mo máa ń ran àwọn aládùúgbò mi lọ́wọ́? Ṣé ilé mi máa ń wà ní mímọ́ tónítóní, ṣé mo sì máa ń tún àyíká mi ṣe?’ Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àdúgbò wa máa túbọ̀ wà ní mímọ́. Tíwọ àtàwọn ará míì bá ń sọ̀rọ̀, o lè béèrè nípa bí ìwà àti ìṣe wọn ṣe mú kí àwọn míì nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ irú bí àwọn mọ̀lẹ́bí, aládùúgbò, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn ọmọléèwé wọn. Ó ṣeé ṣe kó o gbọ́ àwọn ìrírí tó máa fún ẹ lókun.—Éfé. 5:9. w18.06 24 ¶13-14
Friday, June 26
Wákàtí náà ń bọ̀, nígbà tí ẹnikẹ́ni tó bá pa yín máa rò pé ṣe lòun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run. —Jòh. 16:2.
Bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn tó pa Sítéfánù nìyẹn torí wọ́n rò pé Ọlọ́run làwọn ń jà fún. (Ìṣe 6:8, 12; 7:54-60) Bákan náà lónìí, àwọn agbawèrèmẹ́sìn kan máa ń hùwàkiwà, wọ́n sì máa ń pààyàn, wọ́n á ní Ọlọ́run làwọn ń ṣe é fún. Àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn tako òfin Ọlọ́run tí wọ́n láwọn ń jà fún. (Ẹ́kís. 20:13) Ó hàn gbangba pé ibi tí kò yẹ ni ẹ̀rí ọkàn wọn ń darí wọn sí. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa? Àwọn òfin àtàwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tím. 3:16) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa fara balẹ̀ ka Bíbélì déédéé, ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, ká sì máa fi àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ sílò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa kó lè máa tọ́ wa sọ́nà, ká sì lè máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. w18.06 16-17 ¶3-4
Saturday, June 27
Ẹ gba . . . idà ẹ̀mí, ìyẹn, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Éfé. 6:17.
Lásìkò tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀, idà àwọn ọmọ ogun Róòmù máa ń gùn tó àádọ́ta [50] sẹ̀ǹtímítà. Akínkanjú làwọn ọmọ ogun Róòmù tó bá di pé kí wọ́n lo idà, ìdí sì ni pé ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń lo idà yìí tí wọ́n bá ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ jáfáfá sí i lójú ogun. Pọ́ọ̀lù fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé idà tí Jèhófà fún wa. Àmọ́ ó yẹ ká kọ́ bá a ṣe lè lo idà yìí dáadáa tá a bá fẹ́ gbèjà ìgbàgbọ́ wa tàbí tá a bá fẹ́ tún èrò wa ṣe. (2 Kọ́r. 10:4, 5; 2 Tím. 2:15) Kò sídìí kankan fún wa láti máa bẹ̀rù Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Wọ́n lágbára lóòótọ́, àmọ́ a lè ṣẹ́gun wọn, kódà wọn ò ní pẹ́ pa run. Tó bá dìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Jésù máa jù wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Níbẹ̀, wọn ò ní lè pa ẹnikẹ́ni lára, lẹ́yìn náà wọ́n máa pa run pátápátá. (Ìṣí. 20:1-3, 7-10) Inú wa dùn pé a ti mọ ọ̀tá wa, a mọ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tó ń lò, a sì mọ ohun tó fẹ́ ṣe. Ó dájú pé lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà, a máa dúró gbọin-in, Èṣù ò sì ní rí wa gbé ṣe. w18.05 30 ¶15; 31 ¶19-21
Sunday, June 28
Ejò yẹn wá sọ fún obìnrin náà pé: “Ó dájú pé ẹ ò ní kú.”—Jẹ́n. 3:4.
Ó dájú pé Ádámù mọ̀ pé ejò ò lè sọ̀rọ̀. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó fòye gbé e pé ẹ̀dá ẹ̀mí kan ló lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀. (Jẹ́n. 3:1-6) Ádámù àti Éfà ò mọ irú ẹni tí ẹ̀dá ẹ̀mí náà jẹ́ rárá. Síbẹ̀, Ádámù fara mọ́ ohun tí ẹ̀dá ẹ̀mí yìí sọ, ó sì mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Baba rẹ̀ ọ̀run onífẹ̀ẹ́. (1 Tím. 2:14) Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé àwọn ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa ọ̀tá tó tan Ádámù àti Éfà jẹ, ó sì ṣèlérí pé òun máa pa ẹni ibi yìí run. Àmọ́ Jèhófà tún sọ pé kí òun tó pa ọ̀tá yìí run, ọ̀tá yìí máa ta ko àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. (Jẹ́n. 3:15) Jèhófà kò sọ orúkọ áńgẹ́lì tó di ọlọ̀tẹ̀ náà fún wa. Kódà, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] ọdún lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì ni Ọlọ́run tó jẹ́ ká mọ orúkọ tá à ń pe ọ̀tá yẹn lónìí.—Jóòbù 1:6. w18.05 22 ¶1-2
Monday, June 29
Àwọn yìí ló . . . fi ìfaradà so èso.—Lúùkù 8:15.
Tó bá jẹ́ pé ìpínlẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ méso jáde tó o ti ń wàásù máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ, a jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìẹ náà jọ ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nìyẹn. Nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún ni Pọ́ọ̀lù fi wàásù, ó sì ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. (Ìṣe 14:21; 2 Kọ́r. 3:2, 3) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó wàásù fún ni ò kọbi ara sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ọ̀pọ̀ ò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ rárá, kódà àwọn kan ṣe inúnibíni sí i. (Ìṣe 14:19; 17:1, 4, 5, 13) Báwo ni ìwà táwọn Júù hù yìí ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù? Ó sọ pé: “Èmi ń sọ òtítọ́ nínú Kristi . . . mo ní ẹ̀dùn-ọkàn ńláǹlà àti ìrora tí kò dẹ́kun nínú ọkàn-àyà mi.” (Róòmù 9:1-3) Kí ló mú kí ọ̀rọ̀ yìí dun Pọ́ọ̀lù tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù gan-an, ó sì fi tọkàntọkàn wàásù fún àwọn Júù torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. Ó dùn ún pé wọn ò tẹ́wọ́ gba ìhìn rere tó wàásù fún wọn torí Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àánú Ọlọ́run ni wọ́n kọ̀ láti tẹ́wọ́ gbà yẹn. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ìfẹ́ tá a ní sáwọn èèyàn ló ń mú ká máa wàásù fún wọn.—Mát. 22:39; 1 Kọ́r. 11:1. w18.05 13 ¶4-5
Tuesday, June 30
Àníyàn inú ọkàn máa ń mú kó rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ ọ̀rọ̀ rere máa ń mú kó túra ká.—Òwe 12:25.
Pọ́ọ̀lù sọ ohun kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó ní ojúṣe láti máa fúnni níṣìírí náà nílò ìṣírí. Ó sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Aáyun ń yun mí láti rí yín, kí n lè fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀ fún yín, kí a lè fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in; tàbí, kí a kúkú wí pé, kí pàṣípààrọ̀ ìṣírí lè wà láàárín yín, láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kejì, tiyín àti tèmi.” (Róòmù 1:11, 12) Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù tó máa ń fúnni níṣìírí gan-an náà nílò ìṣírí. (Róòmù 15:30-32) Ó yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn ará wa tí wọ́n yááfì àwọn nǹkan kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Àwọn míì tó tún nílò ìṣírí làwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọn ò tíì ṣègbéyàwó torí pé wọ́n fẹ́ ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́r. 7:39) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míì tó tún nílò ìṣírí ni àwọn Kristẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin lójú àtakò tàbí tí wọ́n ń fara da àìsàn.—2 Tẹs. 1:3-5. w18.04 21 ¶3-5