ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es20 ojú ìwé 67-77
  • July

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Wednesday, July 1
  • Thursday, July 2
  • Friday, July 3
  • Saturday, July 4
  • Sunday, July 5
  • Monday, July 6
  • Tuesday, July 7
  • Wednesday, July 8
  • Thursday, July 9
  • Friday, July 10
  • Saturday, July 11
  • Sunday, July 12
  • Monday, July 13
  • Tuesday, July 14
  • Wednesday, July 15
  • Thursday, July 16
  • Friday, July 17
  • Saturday, July 18
  • Sunday, July 19
  • Monday, July 20
  • Tuesday, July 21
  • Wednesday, July 22
  • Thursday, July 23
  • Friday, July 24
  • Saturday, July 25
  • Sunday, July 26
  • Monday, July 27
  • Tuesday, July 28
  • Wednesday, July 29
  • Thursday, July 30
  • Friday, July 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2020
es20 ojú ìwé 67-77

July

Wednesday, July 1

Ẹ máa fi òye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.​—Éfé. 5:17.

“Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la wà yìí. Nǹkan á sì máa burú sí i títí dìgbà tí Jèhófà máa pa ayé búburú yìí run táá sì mú kí àlàáfíà wà kárí ayé. (2 Tím. 3:1) Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Ojú ta ni mò ń wò fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà?’ Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, onísáàmù kan sọ ìdí tó fi yẹ ká máa wojú Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ìṣòro bá dé. (Sm. 123:​1-4) Ó sọ pé bí ìránṣẹ́ kan ṣe máa ń wojú ọ̀gá rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa wojú Jèhófà. Kí ni onísáàmù yìí ní lọ́kàn? Ìránṣẹ́ kan máa ń wojú ọ̀gá rẹ̀ kí ọ̀gá náà lè fún un ní oúnjẹ, kó sì dáàbò bò ó, àmọ́ ìránṣẹ́ kan tún gbọ́dọ̀ máa wojú ọ̀gá rẹ̀ kó lè fòye mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń fẹ́, kó sì ṣe é. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká máa yẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò lójoojúmọ́, ká lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ṣe, ká sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ìgbà yẹn lọkàn wa tó lè balẹ̀ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí ìṣòro bá dé. w18.07 12 ¶1-2

Thursday, July 2

Tí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira, ẹ máa di òmìnira lóòótọ́.​—Jòh. 8:36.

Ó ṣe kedere pé òmìnira tí Jésù ṣèlérí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kọjá òmìnira táwọn èèyàn ń jà fún lónìí. Òmìnira wo ni Jésù ní lọ́kàn? Òmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ìdí sì ni pé ọjọ́ pẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ ti ń pọ́n aráyé lójú. Ká sòótọ́, àwa èèyàn ti di “ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.” (Jòh. 8:34) Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀ṣẹ̀ ló mú ká máa ṣàṣìṣe, òun sì ni kì í jẹ́ ká ṣe ohun tá a mọ̀ pé ó tọ́. Ìyẹn ló sì fà á tí nǹkan fi ń tojú sú wa, tá à ń jìyà, tá a sì ń kú. (Róòmù 6:23) Ó dìgbà tá a bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ká tó lè gbádùn òmìnira tòótọ́ táwọn òbí wa àkọ́kọ́ gbádùn nígbà yẹn. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé “bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi” fi hàn pé àwọn nǹkan kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe, àwọn nǹkan kan sì wà tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún kó tó lè dá wa sílẹ̀ lómìnira. (Jòh. 8:31) Torí pé ọmọlẹ́yìn Kristi ni wá, a ti sẹ́ ara wa, a sì ti pinnu pé ẹ̀kọ́ Kristi làá jẹ́ kó máa darí wa. (Mát. 16:24) Bí Jésù ti ṣèlérí, a máa ní òmìnira tòótọ́ nígbà tá a bá jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́. w18.04 7 ¶14-16

Friday, July 3

Ìwọ nìkan lo mọ ọkàn èèyàn.​—2 Kíró. 6:30.

Jèhófà máa ń gba tàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rò, kódà tí wọn ò bá tiẹ̀ ronú lọ́nà tó tọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà. Ọlọ́run rán wòlíì yìí pé kó lọ kéde ìdájọ́ sórí àwọn ará ìlú Nínéfè. Nígbà táwọn èèyàn náà gbọ́ ìkéde yìí, wọ́n yí pa dà, Ọlọ́run sì pinnu pé òun ò ní pa wọ́n run. Àmọ́, inú Jónà ò dùn sí ohun tí Jèhófà ṣe yẹn rárá. Kódà, ‘inú bí i gan-an’ torí pé ìparun tó sọ tẹ́lẹ̀ kò nímùúṣẹ. Síbẹ̀, Jèhófà mú sùúrù fún Jónà, ó sì ràn án lọ́wọ́ kó lè tún èrò rẹ̀ ṣe. (Jónà 3:10–4:11) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Jónà lóye ìdí tí Jèhófà ò fi pa ìlú yẹn run, nígbà tó sì yá, Jèhófà ní kó kọ ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn sílẹ̀ fún àǹfààní wa. (Róòmù 15:4) Bí Jèhófà ṣe bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò láyé àtijọ́ jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa ń gba tàwa ìránṣẹ́ rẹ̀ rò. Ó mọ ibi tí bàtà ti ń ta kálukú lẹ́sẹ̀. Ó mọ àwọn ohun tó ń gbé wa lọ́kàn sókè, bí nǹkan ṣe rí lára wa àti ibi tá a kù sí. Yàtọ̀ síyẹn, kò “ní jẹ́ kí a dán [wa] wò kọjá ohun tí [a] lè mú mọ́ra.” (1 Kọ́r. 10:13) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí mà tuni nínú o! w19.03 16 ¶6-7

Saturday, July 4

Ohun gbogbo wà ní ìhòòhò, ó sì wà ní gbangba lójú ẹni tí a gbọ́dọ̀ jíhìn fún.​—Héb. 4:13.

Lábẹ́ Òfin Mósè, yàtọ̀ sí pé kí àwọn àgbà ọkùnrin bójú tó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìjọsìn, ojúṣe wọn tún ni láti bójú tó èdèkòyédè tó bá wáyé àtàwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìwà ọ̀daràn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mélòó kan. Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá pààyàn, wọn ò kàn ní pa òun náà láìdúró gbẹ́jọ́. Àwọn àgbààgbà ìlú máa wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa kí wọ́n tó pinnu bóyá kí wọ́n pa á tàbí kí wọ́n má ṣe bẹ́ẹ̀. (Diu. 19:​2-7, 11-13) Onírúurú ọ̀rọ̀ làwọn àgbààgbà yẹn máa ń bójú tó. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń yanjú èdèkòyédè lórí ọ̀rọ̀ ilé àti ilẹ̀, wọ́n sì tún máa ń bá àwọn tọkọtaya yanjú aáwọ̀. (Ẹ́kís. 21:35; Diu. 22:​13-19) Táwọn àgbààgbà yẹn bá ń ṣèdájọ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà sì pa Òfin Ọlọ́run mọ́, gbogbo wọn pátá ló máa ń ṣe láǹfààní, ìyẹn sì máa ń bọlá fún Jèhófà. (Léf. 20:​7, 8; Aísá. 48:​17, 18) Èyí fi hàn pé gbogbo apá ìgbésí ayé wa ni Jèhófà ń kíyè sí. Ó fẹ́ ká máa fìfẹ́ bá ara wa gbé, ká sì máa fi inú kan bá ara wa lò. Bákan náà, gbogbo ohun tá à ń ṣe àtohun tá à ń sọ ni Jèhófà ń kíyè sí, títí kan èyí tá à ń ṣe ní kọ̀rọ̀ inú yàrá wa. w19.02 23 ¶16-18

Sunday, July 5

Ó . . .  jẹ́ kí wọ́n fìyà jẹ òun, àmọ́ kò la ẹnu rẹ̀.​—Àìsá. 53:7.

Ó máa ń ṣòro láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù téèyàn bá ní ìdààmú ọkàn. Láìmọ̀ọ́mọ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sáwọn míì tàbí ká tiẹ̀ máa kanra mọ́ wọn. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kí la lè kọ́ lára Jésù? Jésù ní ìdààmú ọkàn gan-an láwọn oṣù tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Ó mọ̀ pé òun máa jìyà, wọ́n sì máa pa òun. (Jòh. 3:​14, 15; Gál. 3:13) Ní oṣù díẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀, òun fúnra ẹ̀ sọ pé wàhálà ọkàn bá òun. (Lúùkù 12:50) Láwọn ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù sọ pé: “Ọkàn mi dààmú.” Jésù wá gbàdúrà kan tó jẹ́ kó hàn kedere pé ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti pé ó ṣe tán láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Jòh. 12:​27, 28) Nígbà táwọn ọ̀tá Ọlọ́run dé láti wá mú un, Jésù ò bẹ̀rù, ṣe ló jọ̀wọ́ ara ẹ̀ fún wọn. Àwọn ọ̀tá yìí fìyà jẹ ẹ́ gan-an, wọ́n sì pa á ní ìpa ìkà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ní ìdààmú ọkàn tí wọ́n sì fìyà burúkú jẹ ẹ́, ó ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láìjanpata. Kò sí àní-àní pé Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn jẹ́ ọlọ́kàn tútù béèyàn tiẹ̀ ní ìdààmú ọkàn.​—Aísá. 53:10. w19.02 11 ¶14-15

Monday, July 6

Ẹ sì jẹ́ ká gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere.​—Héb. 10:24.

Lásìkò tí nǹkan bá le, ó gba ìgboyà ká tó lè máa wá sípàdé déédéé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan máa ń wá sípàdé déédéé bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní àwọn ìṣòro bí àìlera, ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí ikú èèyàn wọn. Àwọn mí ì sì wà tó ń fojú winá àtakò látọ̀dọ̀ ìdílé wọn tàbí àwọn aláṣẹ, síbẹ̀ wọn ò yé wá sípàdé. Àwọn àpẹẹrẹ yìí ń ṣàǹfààní fún àwọn arákùnrin tó wà lẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ wọn. (Héb. 13:3) Táwọn arákùnrin yìí bá ń gbọ́ pé à ń sin Jèhófà nìṣó láìka àwọn àdánwò tá à ń kojú, ìyẹn á fún wọn lókun, á sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ ní ìgboyà kí wọ́n sì pinnu pé àwọn ò ní fi Jèhófà sílẹ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n nílùú Róòmù, inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó gbọ́ pé àwọn ará ń sin Jèhófà nìṣó láìbọ́hùn. (Fílí. 1:​3-5, 12-14) Kí wọ́n tó dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n tàbí kété lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ ló kọ lẹ́tà sáwọn Hébérù. Nínú lẹ́tà yẹn, ó rọ àwọn Kristẹni olóòótọ́ náà pé kí wọ́n má kọ ìpéjọpọ̀ ara wọn sílẹ̀.​—Héb. 10:25. w19.01 28 ¶9

Tuesday, July 7

Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.​—1 Jòh. 5:19.

Ọgbọ́n bí àwa èèyàn á ṣe máa ronú ká sì máa hùwà bíi tiẹ̀ ni Sátánì ń dá. Ọlọ̀tẹ̀ ni, kò bọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà Jèhófà rárá àti rárá, ó sì tún jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. Onírúurú ọgbọ́n ló ń dá kó lè rí wa mú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn rẹ̀ tó ti sọ dìbàjẹ́ ló yí wa ká. Ó fẹ́ kí wọ́n ba ìwà ọmọlúwàbí wa jẹ́ tàbí kí wọ́n mú ká máa ronú, ká sì máa hùwà bíi tiwọn. (1 Kọ́r. 15:33; àlàyé ìsàlẹ̀) Sátánì tún máa ń fẹ́ ká máa tẹ̀ lé ọgbọ́n èèyàn dípò ọgbọ́n Ọlọ́run. (Kól. 2:8) Àpẹẹrẹ kan ni èrò kan tí Sátánì ń gbé lárugẹ pé owó ni kókó àti pé ẹni tó lówó ló rí ayé wá. Àwọn tó nírú èrò yìí lè rí towó ṣe, àwọn míì sì lè má rí towó ṣe tí wọ́n á fi kú. Èyí ó wù kó jẹ́, irú èrò bẹ́ẹ̀ lè kóni síyọnu. Ìdí sì ni pé eré owó nirú wọn máa ń sá, gbogbo ohun tó bá gbà ni wọ́n sì máa ń ṣe torí kí wọ́n lè lówó. Wọn kì í bìkítà nípa ìdílé wọn àti ìlera wọn, kódà wọn kì í rí ti Ọlọ́run rò tó bá dọ̀rọ̀ owó. (1 Tím. 6:10) A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run tó ń kọ́ wa ká lè ní èrò tó tọ́ nípa owó.​—Oníw. 7:12; Lúùkù 12:15. w19.01 15 ¶6; 17 ¶9

Wednesday, July 8

O káre láé, ẹrú rere àti olóòótọ́! O jẹ́ olóòótọ́ lórí ohun díẹ̀. Màá fi ohun tó pọ̀ síkàáwọ́ rẹ. Bọ́ sínú ayọ̀ ọ̀gá rẹ.​—Mát. 25:21.

Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá di pé ká fúnni níṣìírí, àmọ́ kó tó wá sáyé làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti ń fúnni níṣìírí. Nígbà táwọn ará Ásíríà ń halẹ̀ mọ́ Hesekáyà, ó pe àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti gbogbo èèyàn Júdà lápapọ̀, ó sì fún wọn níṣìírí. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọ̀rọ̀ Hesekáyà ọba Júdà gbé ara wọn ró.” (2 Kíró. 32:​6-8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù fúnra rẹ̀ nílò ìṣírí, síbẹ̀ ó jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa fúnni níṣìírí. Kàkà káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí tù ú nínú, ọ̀rọ̀ kòbákùngbé ni wọ́n ń sọ sí i. Ó wá sọ fún wọn pé ká ní àwọn ni wọ́n wà nírú ipò tóun wà ni, òun ‘ì bá fi ọ̀rọ̀ ẹnu òun fún wọn lókun, ìtùnú ètè òun ì bá sì fún wọn lágbára.’ (Jóòbù 16:​1-5) Nígbà tó yá, Élíhù fún Jóòbù níṣìírí, Jèhófà náà sì tún fún un níṣìírí.​—Jóòbù 33:​24, 25; 36:​1, 11; 42:​7, 10. w18.04 16 ¶6; 17 ¶8-9

Thursday, July 9

Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́.​—Àìsá. 41:10.

Aísáyà ti sọ bí Jèhófà ṣe máa fún àwọn èèyàn rẹ̀ lókun, ó ní: “Jèhófà . . . yóò wá, àní gẹ́gẹ́ bí alágbára, apá rẹ̀ yóò sì máa ṣàkóso fún un.” (Aísá. 40:10) Bíbélì sábà máa ń lo “apá” láti ṣàpẹẹrẹ agbára. Torí náà, bí Aísáyà ṣe sọ pé ‘apá Jèhófà máa bá a ṣàkóso’ ń rán wa létí pé Ọba alágbára ńlá ni Jèhófà. Ó fi agbára rẹ̀ tí kò láàlà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè nígbà àtijọ́, bó sì ṣe ń ṣe títí dòní nìyẹn. (Diu. 1:​30, 31; Aísá. 43:10) Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń fún wa lókun, àmọ́ ní pàtàkì jù lọ, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà táwọn ọ̀tá bá ń ṣenúnibíni sí wa. Láwọn ilẹ̀ kan lónìí, àwọn ọ̀tá máa ń wá gbogbo ọ̀nà láti dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró tàbí kí wọ́n tiẹ̀ gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Síbẹ̀, ẹ̀rù kì í bà wá. Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa fún wa lókun, òun á sì mú ká nígboyà nígbà tó ṣèlérí pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí.”​—Aísá. 54:17. w19.01 5-6 ¶12-13

Friday, July 10

Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.​—Mát. 5:3.

Àwa èèyàn yàtọ̀ sáwọn ẹranko torí pé ó máa ń wu àwa èèyàn láti túbọ̀ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa. (Mát. 4:4) Tó o bá ń tẹ́tí sí i, wàá ní ọgbọ́n àti ìjìnlẹ̀ òye, wàá sì tún láyọ̀. Ọlọ́run ń tọ́ ẹ sọ́nà nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè. (Mát. 24:45) A mà dúpẹ́ o pé à ń gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí yìí lónírúurú! (Aísá. 65:​13, 14) Oúnjẹ tẹ̀mí tàbí ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń fún wa máa ń jẹ́ ká ní ọgbọ́n àti làákàyè, ìyẹn sì máa ń dáàbò boni lónírúurú ọ̀nà. (Òwe 2:​10-14) Bí àpẹẹrẹ, ọgbọ́n àti làákàyè á jẹ́ ká dá àwọn ẹ̀kọ́ èké mọ̀, irú èyí tó sọ pé kò sí Ẹlẹ́dàá. Wọ́n á jẹ́ kó o rí i pé irọ́ gbuu ni pé kéèyàn tó lè láyọ̀, àfi kéèyàn lówó àtàwọn ohun ìní tara. Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò ní jẹ́ kó o máa ro èròkerò tàbí kó o lọ́wọ́ sí ìwàkiwà. Torí náà, túbọ̀ máa wá ọgbọ́n Ọlọ́run, kó o sì máa lo làákàyè! w18.12 20 ¶6-7

Saturday, July 11

Ọjọ́ àwọn èèyàn mi máa dà bí ọjọ́ igi.​—Àìsá. 65:22.

Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí ọjọ́ wa máa gùn “bí ọjọ́ igi”? Àwọn igi kan máa ń lo ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún láyé, àmọ́ kí ẹ̀mí àwa èèyàn tó lè gùn tóyẹn, ìlera wa gbọ́dọ̀ jí pépé. Tí nǹkan bá yí pa dà, tí ayé sì rí bí Aísáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ó dájú pé ayé máa dùn, á sì di Párádísè. Ìgbà yẹn ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí á tó nímùúṣẹ ní kíkún. Ronú nípa báwọn ìlérí yìí ṣe mú kó dá wa lójú pé ayé máa di Párádísè lọ́jọ́ iwájú. Kò ní sí ẹranko tàbí èèyàn táá máa hùwà ẹhànnà. Ojú afọ́jú á là, adití á gbọ́ràn, àwọn arọ á sì máa rìn. Àwọn èèyàn á kọ́lé tí wọ́n á máa gbé, wọ́n á sì gbádùn àwọn igi eléso tí wọ́n bá gbìn. Ẹ̀mí wọn á gùn ju ti igi lọ. Ó ṣe kedere pé ìbùkún ọjọ́ iwájú làwọn ìlérí yìí ń tọ́ka sí. Síbẹ̀, àwọn kan lè sọ pé àsọdùn wà nínú ọ̀rọ̀ yìí, pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ọjọ́ iwájú. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé láìsí tàbí-ṣùgbọ́n ayé yìí máa di Párádísè? Ọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi sọ ló mú kó túbọ̀ dá wa lójú.​—Lúùkù 23:43. w18.12 5 ¶13-15

Sunday, July 12

Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà.​—Róòmù 12:2.

Ọlọ́run dá wa lọ́nà táá mú kó ṣeé ṣe láti yí èrò wa pa dà. Síbẹ̀, ká fi sọ́kàn pé ká tó lè ṣe ìyípadà yìí, àfi ká ṣọ́ ohun tá à ń jẹ́ kó wọnú ọkàn wa àtohun tá à ń ronú lé. Torí náà, tá a bá ń ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, á túbọ̀ dá wa lójú pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan ló tọ̀nà. Ìyẹn á sì mú kó rọrùn láti máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Àmọ́ ká tó lè mú èrò wa bá ti Jèhófà mu, a gbọ́dọ̀ “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.” A ò gbọ́dọ̀ fàyè gba èrò èyíkéyìí tí kò bá ti Ọlọ́run mu nínú ọkàn wa. Ẹ jẹ́ ká fi oúnjẹ ṣàpẹẹrẹ ohun tá à ń sọ yìí. Tẹ́nì kan bá fẹ́ kí ìlera òun túbọ̀ dáa sí i, ó lè pinnu pé òun á máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore. Àmọ́ báwo ni ìlera ẹ̀ ṣe máa rí tó bá tún ń jẹ àwọn oúnjẹ tó ti bà jẹ́? Lọ́nà kan náà, tẹ́nì kan bá ń sapá láti gba èrò Jèhófà, àmọ́ tó tún ń fàyè gba èrò ayé, asán ni gbogbo ìsapá rẹ̀ máa já sí. w18.11 21 ¶14-15

Monday, July 13

Ẹ dúró gbọn-in, kí ẹ fi òtítọ́ di inú yín lámùrè.​—Éfé. 6:14.

Pinnu pé wàá jẹ́ kí òtítọ́ máa darí ìgbésí ayé rẹ lójoojúmọ́. Bíbélì fi òtítọ́ wé àmùrè tàbí bẹ́líìtì tí wọ́n máa ń dè mọ́ abẹ́nú. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn ọmọ ogun máa ń fi bẹ́líìtì de abẹ́nú wọn kó lè dáàbò bo ikùn wọn. Àmọ́ kí bẹ́líìtì náà tó lè dáàbò bo ọmọ ogun kan, ó gbọ́dọ̀ dè é pinpin torí tí bẹ́líìtì rẹ̀ bá ṣe dẹngbẹrẹ, kò ní ṣe é láǹfààní kankan. Báwo ni òtítọ́ tá a fi wé bẹ́líìtì ṣe ń dáàbò bò wá? Tá a bá ń jẹ́ kí òtítọ́ darí wa nígbà gbogbo, a ò ní máa ronú lọ́nà tí kò tọ́, ìyẹn á sì jẹ́ ká máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Tá a bá kojú àdánwò, òtítọ́ Bíbélì máa jẹ́ ká dúró lórí ìpinnu wa láti ṣe ohun tó tọ́. Ó dájú pé ọmọ ogun kan ò ní lọ sójú ogun láìde bẹ́líìtì rẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwa náà gbọ́dọ̀ pinnu pé a ò ní bọ́ bẹ́líìtì òtítọ́ láé tàbí ká jẹ́ kó ṣe dẹngbẹrẹ. Ó yẹ ká dè é mọ́ abẹ́nú wa pinpin, ìyẹn ni pé ká jẹ́ kí òtítọ́ máa darí wa lójoojúmọ́. w18.11 12 ¶15

Tuesday, July 14

Ra òtítọ́, má sì tà á láé. ​—Òwe 23:23.

A máa sapá gan-an ká tó lè kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yááfì ohunkóhun ká lè kọ́ ẹ̀kọ́ yìí. Ìdí nìyẹn tí ẹni tó kọ ìwé Òwe fi sọ pé, tá a bá ti “ra” òtítọ́ tàbí tá a ti mọ “òtítọ́,” ó yẹ ká ṣọ́ra ká má “tà á” tàbí lédè míì, ká má jẹ́ kó bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Tí nǹkan kan bá tiẹ̀ jẹ́ ọ̀fẹ́, kò túmọ̀ sí pé kò ní ná wa ní ohunkóhun. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí ‘rà’ nínú Òwe 23:23 tún lè túmọ̀ sí kí nǹkan kan di tiwa. Ìtumọ̀ tí ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí ní ni pé téèyàn bá fẹ́ ní ohun kan tó ṣe pàtàkì, èèyàn gbọ́dọ̀ sapá tàbí kó yááfì nǹkan kan kó tó lè ní nǹkan ọ̀hún. Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí. Ká sọ pé ẹnì kan ń pín ọ̀gẹ̀dẹ̀ ọ̀fẹ́ lọ́jà. Ó dájú pé ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà ò ní ṣàdédé fò sínú ilé wa, a gbọ́dọ̀ sapá láti lọ síbi tí wọ́n ti ń pín in ká tó lè rí i gbà. Òótọ́ ni pé ọ̀fẹ́ ni ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà, àmọ́ a gbọ́dọ̀ lọ sọ́jà, ká tó lè gbà á. Lọ́nà kan náà, a ò nílò owó ká tó lè ra òtítọ́, àmọ́ a gbọ́dọ̀ sapá ká tó lè kọ́ òtítọ́ yìí. w18.11 4 ¶4-5

Wednesday, July 15

Ojú rẹ̀ tàn bí oòrùn, aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sì tàn yòò.​—Mát. 17:2.

Jésù mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tó lọ sórí òkè ńlá kan. Ibẹ̀ ni wọ́n wà nígbà tí wọ́n rí ìran kan tó kàmàmà. Wọ́n rí i tí ojú Jésù ń tàn yanran, tí aṣọ rẹ̀ sì ń kọ mànà. Wọ́n tún kíyè sí àwọn méjì kan tó ṣàpẹẹrẹ Mósè àti Èlíjà tí wọ́n ń bá Jésù sọ̀rọ̀ nípa ikú àti àjíǹde rẹ̀. (Lúùkù 9:​29-32) Lẹ́yìn ìyẹn, ìkùukùu tó mọ́lẹ̀ yòò ṣíji bò wọ́n, wọ́n sì gbọ́ ohùn Ọlọ́run fúnra rẹ̀! Ìran yẹn jẹ́ kó ṣe kedere pé ògo àti agbára Jésù máa kàmàmà nígbà tó bá di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Kò sí àní-àní pé ìran yẹn fún Jésù lókun, ó sì mú kó gbára dì fún ikú oró tó máa kú. Yàtọ̀ síyẹn, ó mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ túbọ̀ lágbára, ó sì fún wọn níṣìírí kí wọ́n lè fara da àdánwò, kí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láṣeyọrí. Ní nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa ìran ológo yẹn, ìyẹn sì fi hàn pé ìran náà ṣì wà lọ́kàn rẹ̀ digbí, kò gbàgbé rárá.​—2 Pét. 1:​16-18. w19.03 10 ¶7-8

Thursday, July 16

À ń dámọ̀ràn ara wa bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, . . . nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́. ​—2 Kọ́r. 6:​4, 7.

Ọ̀nà wo làwa Kristẹni tòótọ́ máa ń gbà fi hàn pé a yàtọ̀ sáwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn èké? Ọ̀nà kan ni pé a máa ń “sọ òtítọ́.” (Sek. 8:​16, 17) A ò ní parọ́ fún ẹnikẹ́ni, ẹni náà ì báà jẹ́ àjèjì, ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́, ọ̀rẹ́ wa tàbí èèyàn wa pàápàá. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, o lè fẹ́ káwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ẹgbẹ́ gba tìẹ. Kò yẹ kó o ṣe bíi tàwọn ọ̀dọ́ kan tó máa ń ṣojú ayé. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n á máa ṣe dáadáa lójú àwọn òbí wọn àti lójú àwọn ará ìjọ, àmọ́ ìwà wọn kì í jọ ti ọmọlúàbí tí wọ́n bá wà pẹ̀lú àwọn èèyàn ayé, ohun tí wọ́n sì ń gbé sórí ìkànnì àjọlò kò jọ ti ìránṣẹ́ Jèhófà. Wọ́n rò pé àwọn lè tan àwọn òbí wọn àtàwọn ará ìjọ, káwọn sì tún tan Jèhófà. (Sm. 26:​4, 5) Jèhófà mọ̀ tẹ́nì kan bá kàn ń ‘fi ètè lásán bọlá fún un, ṣùgbọ́n tí ọkàn rẹ̀ jìnnà réré sí i.’ (Máàkù 7:6) Ó máa dáa kó o fi ìmọ̀ràn Bíbélì sọ́kàn pé: “Má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n kí o bẹ̀rù Jèhófà láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”​—Òwe 23:17. w18.10 9 ¶14-15

Friday, July 17

Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́, ẹni tó bá wà nínú ìfẹ́ ṣì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀. ​—1 Jòh. 4:16.

Ìfẹ́ ló so àwa èèyàn Ọlọ́run pọ̀ kárí ayé, èyí sì mú ká dà bí ọmọ ìyá. (1 Jòh. 4:21) Kò dìgbà tá a bá ṣe nǹkan ńlá ká tó lè fi ìfẹ́ yìí hàn. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn nǹkan kéékèèké tó lè dà bíi pé kò jọjú tá à ń ṣe fáwọn míì ló máa ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa. Bí àpẹẹrẹ, a lè sọ̀rọ̀ tó máa gbé àwọn míì ró tàbí ká ṣoore fún wọn. Torí náà, tá a bá jẹ́ onínúure, tá a sì ń gba tàwọn míì rò, àá “di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfé. 5:1) Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀ láìkù síbì kan. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára . . . , nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi.” (Mát. 11:​28, 29) Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, tá à ń “fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀,” a máa rí ojú rere Jèhófà, ayọ̀ tá a sì máa ní á kọjá àfẹnusọ. (Sm. 41:1) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe ohun tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́, ká máa gba tàwọn míì rò nínú ìdílé, nínú ìjọ àti lóde ẹ̀rí. w18.09 28 ¶1-2

Saturday, July 18

Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá.​—1 Kọ́r. 3:9.

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà táwa èèyàn Ọlọ́run ń gbà bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ ni pé, a máa ń ran àwọn ará wa lọ́wọ́ nígbà àjálù. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará máa ń fi owó ṣètìlẹyìn fáwọn tí àjálù bá. (Jòh. 13:​34, 35; Ìṣe 11:​27-30) Ohun míì tá a lè ṣe ni pé ká yọ̀ǹda ara wa fún iṣẹ́ ìmọ́tótó níbi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀ tàbí ká bá wọn tún àwọn ibi tó bà jẹ́ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, omíyalé ba ilé Arábìnrin Gabriela tó wá láti orílẹ̀-èdè Poland jẹ́. Àmọ́ inú rẹ̀ dùn nígbà táwọn ará tó wà láwọn ìjọ ìtòsí wá ràn án lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Mi ò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo pàdánù, ó ṣe tán, àwọn nǹkan tara ni. Àmọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí mo jèrè. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé kò síbòmíì tó dà bí ètò Ọlọ́run tá a wà yìí, èyí sì máa ń fún mi láyọ̀ gan-an.” Ọ̀pọ̀ àwọn tírú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí náà gbà pẹ̀lú ohun tí arábìnrin yìí sọ. Àwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ Jèhófà lọ́nà yìí máa ń ní ìbàlẹ̀ ọkàn, wọ́n sì máa ń láyọ̀.​—Ìṣe 20:35; 2 Kọ́r. 9:​6, 7. w18.08 26 ¶12

Sunday, July 19

Dáàbò bo ọkàn rẹ.​—Òwe 4:23.

Tá a bá máa dáàbò bo ọkàn wa, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn nǹkan tó lè wu wá léwu, ká sì gbé ìgbésẹ̀ láìjáfara láti dáàbò bo ara wa. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “fi ìṣọ́ ṣọ́” tàbí dáàbò bò rán wa létí iṣẹ́ táwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń ṣe. Lásìkò Ọba Sólómọ́nì, orí ògiri ìlú làwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń wà tí wọ́n á máa ṣọ́ ohun tó ń lọ, tí wọ́n bá sì kó fìrí ewu, wọ́n á ké jáde kí àwọn aráàlú lè mọ̀. Àpẹẹrẹ yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tó yẹ ká ṣe kí Sátánì má bàa sọ ọkàn wa dìbàjẹ́. Láyé àtijọ́, àwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣọ́bodè ìlú. (2 Sám. 18:​24-26) Bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ yìí mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti dáàbò bo ìlú, wọ́n máa ń rí i pé ẹnubodè ìlú wà ní títì pa nígbàkigbà táwọn ọ̀tá bá sún mọ́ tòsí. (Neh. 7:​1-3) Bákan náà lónìí, Sátánì máa ń wọ́nà àtidarí ọkàn wa, èrò wa, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan àti ìfẹ́ ọkàn wa. Àmọ́, ẹ̀rí ọkàn tá a fi Bíbélì kọ́ máa ń ṣiṣẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣọ́, ó máa ń kìlọ̀ fún wa nígbà tí Sátánì bá gbé ìṣe rẹ̀ dé. Torí náà, nígbàkigbà tí ẹ̀rí ọkàn wa bá kìlọ̀ fún wa, ó yẹ ká tẹ́tí sí i, ká sì ti ilẹ̀kùn ọkàn wa pa. w19.01 17 ¶10-11

Monday, July 20

Kí wọ́n di òjíṣẹ́, nítorí wọn ò ní ẹ̀sùn lọ́rùn.​—1 Tím. 3:10.

A kì í fi èrò wa tàbí àṣà ìbílẹ̀ wa gbé àwọn ọ̀dọ́kùnrin yẹ̀ wò bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n, kàkà bẹ́ẹ̀ ìlànà Bíbélì là ń lò. (2 Tím. 3:​16, 17) Táwọn alàgbà bá ń lo èrò wọn tàbí àṣà ìbílẹ̀ wọn láti gbé àwọn ọ̀dọ́kùnrin yẹ̀ wò, wọ́n lè fi àǹfààní iṣẹ́ ìsìn du àwọn tó kúnjú ìwọ̀n fún àǹfààní náà. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè kan, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan wà tó dáńgájíá, fún ìdí yìí àwọn alàgbà fún un láwọn ojúṣe pàtàkì nínú ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà yẹn gbà pé ọ̀dọ́kùnrin náà kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà níbàámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́, síbẹ̀ wọn ò dámọ̀ràn rẹ̀ láti di alàgbà. Díẹ̀ lára àwọn alàgbà tó dàgbà láàárín wọn sọ pé arákùnrin náà ṣì kéré lójú àti pé àwọn míì lè máa wò ó pé ó ti kéré jù láti di alàgbà. Àbí ẹ ò rí nǹkan, wọn ò dámọ̀ràn arákùnrin náà torí wọ́n gbà pé ó kéré lójú! Ìròyìn fi hàn pé ọ̀pọ̀ ló ní irú èrò yìí kárí ayé. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an ká máa lo ìlànà Ìwé Mímọ́ dípò èrò wa tá a bá ń gbé àwọn arákùnrin yẹ̀ wò. Ọ̀nà kan nìyẹn tá a lè gbà tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé ká má ṣe fi ìrísí dáni lẹ́jọ́.​—Jòh. 7:24. w18.08 12 ¶16-17

Tuesday, July 21

Tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀rọ̀ láì tíì gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀, ìwà òmùgọ̀ ni, ó sì ń kó ìtìjú báni.​—Òwe 18:13.

Ewu wà níbẹ̀ tá a bá ń tètè fi àwọn ìsọfúnni tí kò dá wa lójú ránṣẹ́ sáwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ilẹ̀ kan wà tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. Àwọn alátakò wa láwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè mọ̀ọ́mọ̀ gbé àwọn ìsọfúnni kan sáfẹ́fẹ́ kí wọ́n lè dẹ́rù bà wá, ká má sì fọkàn tán àwọn ará wa mọ́. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa nígbà ìjọba Soviet Union. Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ KGB bẹ̀rẹ̀ sí í tan irọ́ kálẹ̀, wọ́n sọ pé àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú ti fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, wọ́n sì ti dalẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló gba ìròyìn èké yìí gbọ́, èyí sì mú kí wọ́n fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ wọn pa dà sínú ètò Ọlọ́run nígbà tó yá, àmọ́ àwọn kan ò pa dà torí wọ́n ti jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn rì. (1 Tím. 1:19) Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa? Tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ kan tí kò dáa nípa àwọn ará wa tàbí ọ̀rọ̀ kan tí kò dá ẹ lójú, má ṣe tan irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kálẹ̀. Àwọn tí kò gbọ́n ló máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, torí náà, rí i dájú pé o rí àrídájú ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tó o bá gbọ́. w18.08 4 ¶8

Wednesday, July 22

Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, o máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè. ​—Lúùkù 23:43.

Ní èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì, wọ́n kì í sábà lo àmì ìdánudúró. Ìyẹn wá mú kéèyàn béèrè pé: Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé, “Mo sọ fún ọ, lónìí ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè”? Àbí ohun tó ń sọ ni pé, “Mo sọ fún ọ lónìí, ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè”? Ẹ má gbàgbé pé kí Jésù tó kú ló ti sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ọmọ ènìyàn yóò wà ní àárín ilẹ̀ ayé fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.” (Mát. 12:40; 16:21; 17:​22, 23; Máàkù 10:34; Ìṣe 10:​39, 40) Torí náà, Jésù ò lọ sí Párádísè kankan lọ́jọ́ tí òun àti ọ̀daràn yẹn kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé Jésù wà nínú “Hédíìsì [tàbí Isà Òkú]” fún ọjọ́ mélòó kan títí dìgbà tí Ọlọ́run jí i dìde. (Ìṣe 2:​31, 32) Ó dájú pé ọ̀daràn yẹn ò mọ̀ pé Jésù ti bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ dá májẹ̀mú pé wọ́n máa jọba pẹ̀lú òun ní ọ̀run. (Lúùkù 22:29) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀daràn náà ò tíì ṣèrìbọmi. (Jòh. 3:​3-6, 12) Torí náà, Párádísè orí ilẹ̀ ayé ni Jésù ṣèlérí fún un. w18.12 6 ¶17-18, 20-21

Thursday, July 23

Ṣe ọlọ́run kan fún wa tó máa ṣáájú wa, torí a ò mọ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí Mósè yìí.​—Ẹ́kís. 32:1.

Kò pẹ́ tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lófin ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn ère ọmọ màlúù oníwúrà! Ṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn tan ara wọn jẹ, wọ́n rò pé àwọn ṣì ń ṣe ti Jèhófà. Kódà, Áárónì sọ fún wọn pé “àjọyọ̀ fún Jèhófà” ni wọ́n ń ṣe. Báwo ni ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣe rí lára Jèhófà? Ó dùn ún gan-an, ó sì sọ fún Mósè pé wọ́n ti “ba ara wọn jẹ́,” wọ́n sì ‘kúrò ní ọ̀nà tí [òun] pa láṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa rìn.’ Èyí mú kí ‘ìbínú Jèhófà’ ru débi pé ó ronú àtipa wọ́n run. (Ẹ́kís. 32:​5-10) Jèhófà pinnu pé òun ò ní pa gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run. (Ẹ́kís. 32:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Áárónì ló bá wọn ṣe ère náà, síbẹ̀ ó ronú pìwà dà, ó sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Léfì tó fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló pàdánù ẹ̀mí wọn lọ́jọ́ yẹn torí ìbọ̀rìṣà, Jèhófà ṣèlérí pé òun máa bù kún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ adúróṣinṣin.​—Ẹ́kís. 32:​26-29. w18.07 20 ¶13-16

Friday, July 24

Ẹ ṣọ́ra fún àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa . . . kí wọn níbi ọjà . . . àti ibi tó lọ́lá jù níbi oúnjẹ alẹ́.​—Lúùkù 20:46.

Ojúure ta ló yẹ ká máa wá? Káwọn kan lè rí ojúure èèyàn, wọ́n máa ń kàwé rẹpẹtẹ tàbí kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe rọ́wọ́ mú nídìí ìṣòwò tàbí lágbo àwọn òṣèré. Àmọ́ àwa kì í ṣe bẹ́ẹ̀, dípò ìyẹn, Pọ́ọ̀lù sọ ojúure ẹni tó yẹ ká máa wá, ó ní: “Nísinsìnyí tí ẹ ti wá mọ Ọlọ́run, tàbí kí a kúkú sọ pé nísinsìnyí tí ẹ ti wá di mímọ̀ fún Ọlọ́run, èé ti rí tí ẹ tún ń padà sẹ́yìn sí àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ aláìlera àti akúrẹtẹ̀, tí ẹ sì ń fẹ́ láti tún padà sìnrú fún wọn?” (Gál. 4:9) Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ mà nìyẹn o, pé Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run lè mọ̀ wá! Kódà, ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì wù ú pé ká jẹ́ ọ̀rẹ́ òun. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tiẹ̀ sọ pé, “ó máa ń pàfiyèsí sí wa kó lè fojúure hàn sí wa.” Torí náà, tá a bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, ó dájú pé ìgbésí ayé wa máa nítumọ̀.​—Oníw. 12:​13, 14. w18.07 8 ¶3-4

Saturday, July 25

Mò ń ronú lórí àwọn ìránnilétí rẹ.​—Sm. 119:99.

Kí àwọn òfin Jèhófà tó lè ṣe wá láǹfààní, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn òfin Jèhófà, ká sì mọyì wọn. (Ámósì 5:15) Báwo la ṣe lè ṣe é? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká kọ́ bá a ṣe lè máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé o kì í rí oorun sùn dáadáa, o wá lọ rí dókítà. Dókítà wá ka àwọn oúnjẹ aṣaralóore tó yẹ kó o máa jẹ, ó ní kó o máa ṣe eré ìdárayá, kó o sì ṣe àwọn àyípadà kan. Nígbà tó o ṣe àwọn nǹkan yẹn, o bẹ̀rẹ̀ sí í rí oorun sùn. Ó dájú pé inú rẹ máa dùn gan-an, wàá sì mọyì ohun tí dókítà náà ṣe fún ẹ. Lọ́nà kan náà, àwọn òfin tí Ẹlẹ́dàá fún wa máa ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀, ó sì ń dáàbò bò wá ká má bàa kó sí páńpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ká sì jìyà àbájáde rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ ronú nípa àǹfààní tó wà nínú pípa òfin Ọlọ́run mọ́ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn máa gbèrò ibi, irọ́ pípa, olè jíjà, ìṣekúṣe, ìwà ipá àti ìbẹ́mìílò. (Òwe  6:​16-19; Ìṣí. 21:8) Nígbà táwa náà bá ń rí àǹfààní tó wà nínú pípa òfin Ọlọ́run mọ́, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká sì mọyì àwọn òfin tó fún wa. w18.06 17 ¶5-6

Sunday, July 26

Ṣé ìwọ ni Ọba Àwọn Júù? ​—Jòh. 18:33.

Ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa ba Pílátù pé Jésù lè dá rògbòdìyàn sílẹ̀, kó sì mú káwọn Júù ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba Róòmù. Àmọ́ Jésù dá a lóhùn pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòh. 18:36) Jésù ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú rárá torí pé ọ̀run ni Ìjọba rẹ̀ ti máa ṣàkóso. Ó tún sọ fún Pílátù pé torí kóun “lè jẹ́rìí sí òtítọ́” lòun ṣe wá sáyé. (Jòh. 18:37) Iṣẹ́ tí Jèhófà rán Jésù ló gbájú mọ́, táwa náà bá gbájú mọ́ iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa, a ò ní gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú èyíkéyìí, kódà a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ọkàn wa. Ká sòótọ́, èyí ò rọrùn. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn lágbègbè wa ló túbọ̀ ń hùwà jàgídíjàgan, ṣe ni wọ́n ń gbé orílẹ̀-èdè wọn lárugẹ, wọ́n sì gbà pé nǹkan máa sàn tó bá jẹ́ pé ẹni tó jẹ́ ẹ̀yà wọn ló ń ṣàkóso. Àmọ́ a dúpẹ́ pé àwọn ará gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, èyí sì jẹ́ kí wọ́n wà níṣọ̀kan. Wọ́n gbà pé Ọlọ́run nìkan ló lè fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ, kó sì yanjú gbogbo àwọn ìṣòro míì tá à ń kojú.” w18.06 4-5 ¶6-7

Monday, July 27

Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, ó sì máa sá kúrò lọ́dọ̀ yín.​—Jém. 4:7.

Ìwé mẹ́ta péré nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ló mẹ́nu kan Sátánì tó túmọ̀ sí “Alátakò.” Àwọn ìwé náà ni Kíróníkà Kìíní, Jóòbù àti Sekaráyà. Kí nìdí tí Bíbélì ò fi sọ púpọ̀ nípa ọ̀tá wa ṣáájú kí Mèsáyà tó dé? Jèhófà ò sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa nípa Sátánì nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ó ṣe tán, ìdí pàtàkì tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù fi wà lákọọ́lẹ̀ ni pé Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn dá Mèsáyà mọ̀, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé e. (Lúùkù 24:44; Gál. 3:24) Lẹ́yìn tí Mèsáyà dé, Jèhófà lo òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ láti jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan tá a mọ̀ báyìí nípa Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀. Ìyẹn sì bá a mu gẹ́lẹ́ torí Jésù àtàwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n á jọ ṣàkóso ni Jèhófà máa lò láti pa Sátánì àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ run. (Róòmù 16:20; Ìṣí. 17:14; 20:10) Ó níbi tí agbára Èṣù mọ. Ọkàn wa balẹ̀ torí pé Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì wà lẹ́yìn wa gbágbáágbá. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ wọn, a máa borí ọ̀tá wa. w18.05 22-23 ¶2-4

Tuesday, July 28

Ó ń mú gbogbo ẹ̀ka tí kì í so èso nínú mi kúrò.​—Jòh. 15:2.

Kìkì àwọn tó bá ń so èso ni Jèhófà máa kà sí ìránṣẹ́ rẹ̀. (Mát. 13:23; 21:43) Àmọ́, ṣé àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì wá sínú òtítọ́ ni èso tí Jésù ní lọ́kàn nínú àkàwé tó wà ní Jòhánù 15:​1-5? Rárá o. (Mát. 28:19) Torí pé tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ẹ̀ka tí kò méso jáde ni àwọn ará tó ń fòótọ́ inú sin Jèhófà, tí wọn ò sì sọ ẹnikẹ́ni di ọmọ ẹ̀yìn torí pé àwọn èèyàn ò tẹ́tí sí wọn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Ó dájú pé kò rí bẹ́ẹ̀! Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ kò ní pa àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ tì torí pé àwọn tá à ń wàásù fún kọ̀ láti di ọmọ ẹ̀yìn. Ó ṣe tán, a ò lè fi tipátipá sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Ó sì dájú pé ohun tágbára wa gbé ni Jèhófà máa ń béèrè lọ́wọ́ wa. (Diu. 30:​11-14) Kí wá ni èso tó yẹ ká so? Ó dájú pé iṣẹ́ kan tí gbogbo wa lè ṣe ni èso yẹn ń tọ́ka sí. Iṣẹ́ wo nìyẹn? Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni.​—Mát. 24:14. w18.05 14 ¶8-9

Wednesday, July 29

Ọ̀dọ̀ Èṣù bàbá yín lẹ ti wá, . . . òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́. ​—Jòh. 8:44.

Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn pọ̀ lọ jàra nínú ayé lónìí. Wọ́n lè máa pè wọ́n ní pásítọ̀, àlùfáà, rábì, wòlíì tàbí àwọn orúkọ oyè míì. Bíi tàwọn aṣáájú ẹ̀sìn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, wọ́n ń “tẹ òtítọ́” tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “rì,” wọ́n sì ń “fi irọ́ ṣe pàṣípààrọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.” (Róòmù 1:​18, 25) Lára àwọn ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n ń gbé lárugẹ ni ẹ̀kọ́ àtúnwáyé, “ìgbàlà lẹ́ẹ̀kan, ìgbàlà gbogbo ìgbà,” àti pé ọkàn èèyàn kì í kú. Wọ́n tún ń kọ́ni pé Ọlọ́run ò ní bínú tí ọkùnrin àti ọkùnrin bá fẹ́ ara wọn tàbí tí obìnrin àti obìnrin bá fẹ́ ara wọn. Àwọn olóṣèlú náà máa ń fi irọ́ tan àwọn èèyàn jẹ. Irọ́ kàbìtì kan tí wọ́n ṣì máa pa fáwọn èèyàn lọ́jọ́ iwájú ni pé ọwọ́ àwọn ti tẹ “àlàáfíà àti ààbò!” Ṣùgbọ́n, “ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn.” Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká gba àwọn olóṣèlú yìí gbọ́ tí wọ́n bá ń sọ pé ká fọkàn balẹ̀, kò séwu mọ́! Ká sòótọ́, a “mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru.”​—1 Tẹs. 5:​1-4. w18.10 7-8 ¶6-8

Thursday, July 30

Ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tó jẹ́ aláìlera, ẹ sì gbọ́dọ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa sọ́kàn, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”​—Ìṣe 20:35.

Jésù Kristi máa ń lo àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn ọmọ aládé” tó jẹ́ ara àgùntàn mìíràn láti fún wa níṣìírí àti ìtọ́sọ́nà. Ìdí ni pé a máa ń soríkọ́, a sì máa ń rẹ̀wẹ̀sì nígbà míì. Bó ti wù kó rí, àwọn alàgbà yìí kì í ṣe “ọ̀gá” lórí ìgbàgbọ́ wa. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n “jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú wa, wọ́n sì fẹ́ ká láyọ̀. (Aísá. 32:​1, 2; 2 Kọ́r. 1:24) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn alàgbà. Nígbà tó kọ̀wé sáwọn ará Tẹsalóníkà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí, ó ní: “Ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín, ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún wa.” (1 Tẹs. 2:8) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn alàgbà ìjọ Éfésù sọ̀rọ̀, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan ni wọ́n á fi máa fún àwọn ará níṣìírí, ìdí nìyẹn tó fi sọ ọ̀rọ̀ ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. w18.04 21-22 ¶6-8

Friday, July 31

Jèhófà ni Ẹ̀mí náà, ibi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, òmìnira á wà níbẹ̀.​—2 Kọ́r. 3:17.

Tá a bá máa jadùn òmìnira yìí, a gbọ́dọ̀ “yíjú sí Jèhófà,” ìyẹn ni pé, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àárín àwa àti Jèhófà gún régé. (2 Kọ́r. 3:16) Dípò káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé Mósè ronú nípa àǹfààní tí wọ́n ní láti jọ́sìn Jèhófà, àwọn nǹkan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní Íjíbítì ló gbà wọ́n lọ́kàn. Ṣe ló dà bíi pé ìbòjú bo ọkàn wọn àti èrò orí wọn lẹ́yìn tí wọ́n kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, ọkàn wọn sì yigbì débi pé kò sóhun míì tí wọ́n ń rò kọjá nǹkan tara. (Héb. 3:​8-10) Òmìnira tí ẹ̀mí Jèhófà ń fúnni kọjá òmìnira èyíkéyìí téèyàn lè fúnni. Ẹ̀mí Jèhófà máa mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, yàtọ̀ síyẹn, ó ń mú ká bọ́ lọ́wọ́ ìsìn èké àtàwọn àṣà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, kò sì sẹ́ni tó lè dá wa sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn nǹkan yìí. (Róòmù 6:23; 8:2) Ó dájú pé òmìnira tí kò lẹ́gbẹ́ lèyí jẹ́! Èèyàn lè jadùn òmìnira yìí kódà bó tiẹ̀ wà lẹ́wọ̀n tàbí tó jẹ́ ẹrú.​—Jẹ́n. 39:​20-23. w18.04 9 ¶3-5

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́