ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es20 ojú ìwé 78-88
  • August

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • August
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Saturday, August 1
  • Sunday, August 2
  • Monday, August 3
  • Tuesday, August 4
  • Wednesday, August 5
  • Thursday, August 6
  • Friday, August 7
  • Saturday, August 8
  • Sunday, August 9
  • Monday, August 10
  • Tuesday, August 11
  • Wednesday, August 12
  • Thursday, August 13
  • Friday, August 14
  • Saturday, August 15
  • Sunday, August 16
  • Monday, August 17
  • Tuesday, August 18
  • Wednesday, August 19
  • Thursday, August 20
  • Friday, August 21
  • Saturday, August 22
  • Sunday, August 23
  • Monday, August 24
  • Tuesday, August 25
  • Wednesday, August 26
  • Thursday, August 27
  • Friday, August 28
  • Saturday, August 29
  • Sunday, August 30
  • Monday, August 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2020
es20 ojú ìwé 78-88

August

Saturday, August 1

Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ rẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.​—Róòmù 5:8.

Láwọn ìpàdé wa, a máa ń rán ara wa létí nípa àwọn ohun tí Jèhófà àti Jésù ti ṣe fún wa. Torí pé a mọyì ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wa, a máa ń sapá láti fara wé Jésù bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa ojoojúmọ́. (2 Kọ́r. 5:​14, 15) Bákan náà, a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, a sì máa ń yìn ín torí pé ó rà wá pa dà. Ọ̀nà kan tá à ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni bá a ṣe ń dáhùn nípàdé. A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ tá a bá ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan kan nítorí wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, onírúurú nǹkan la máa ń yááfì ká lè pésẹ̀ sáwọn ìpàdé wa. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìjọ ló máa ń ṣe ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ wọn lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ nígbà tó ti rẹ àwọn èèyàn. A sì tún máa ń ṣe ìpàdé mí ì ní òpin ọ̀sẹ̀ lásìkò tọ́pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́ sinmi. Ṣé Jèhófà máa ń rí ìsapá tá à ń ṣe láti wá sípàdé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wá? Ó dájú pé ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀! Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, bí ohun tá a yááfì bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa túbọ̀ mọyì ìfẹ́ tá a ní fún un.​—Máàkù 12:​41-44. w19.01 29 ¶12-13

Sunday, August 2

Nígbà tí Olúwa tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é.​—Lúùkù 7:13.

Jésù fúnra rẹ̀ kojú àwọn ìṣòro kan náà táwa èèyàn máa ń ní. Bí àpẹẹrẹ, inú ìdílé tí wọn ò ti fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ ni Jésù dàgbà sí, iṣẹ́ alágbára tó sì ń tánni lókun ni Jésù kọ́ lọ́dọ̀ Jósẹ́fù tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀. (Mát. 13:55; Máàkù 6:3) Ó jọ pé Jósẹ́fù kú kí Jésù tó parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé Jésù náà mọ bó ṣe máa ń rí lára téèyàn ẹni bá kú. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù tún mọ bó ṣe máa ń rí téèyàn bá ń gbé nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. (Jòh. 7:5) Ó dájú pé àwọn nǹkan tí Jésù kojú yìí á jẹ́ kó lóye ohun tójú àwọn èèyàn ń rí àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé Jésù mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn. Kì í ṣe torí pé ó pọn dandan fún Jésù láti ṣe iṣẹ́ ìyanu ló fi ń ṣe é. Dípò bẹ́ẹ̀, àánú àwọn tó ń jìyà ló máa ń ṣe é, á sì ràn wọ́n lọ́wọ́. (Mát. 20:​29-34; Máàkù 1:​40-42) Jésù bá àwọn èèyàn kẹ́dùn, ìdí nìyẹn tó fi ràn wọ́n lọ́wọ́.​—Máàkù 7:​32-35; Lúùkù 7:​12-15. w19.03 16 ¶10-11

Monday, August 3

Ẹ máa fara dà á fún ara yín. ​—Kól. 3:13.

Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ẹ ronú nípa ohun táá máa jà gùdù lọ́kàn ẹ̀. Ṣé ó máa jẹ́ olóòótọ́ títí dojú ikú? Ohun tó bá ṣe ló máa pinnu bóyá aráyé máa rí ìgbàlà tàbí wọn ò ní rí i. (Róòmù 5:​18, 19) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, ìpinnu tó bá ṣe lè sọ orúkọ Baba rẹ̀ di mímọ́ tàbí kó tàbùkù sí i. (Jóòbù 2:4) Nígbà tóun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jọ ń jẹun lálẹ́ ọjọ́ yẹn, “awuyewuye gbígbónájanjan kan” bẹ̀rẹ̀ láàárín àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ “lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.” Jésù ò kanra mọ́ wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló fohùn pẹ̀lẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀. Bó ti wù kó rí, Jésù ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó ṣàlàyé bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe síra wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣàlàyé fún wọn tẹ́lẹ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn ló gbóríyìn fún wọn fún bí wọ́n ṣe dúró ti òun nígbà ìṣòro. (Lúùkù 22:​24-28; Jòh. 13:​1-5, 12-15) A lè fara wé Jésù, ká sì ṣe sùúrù kódà tá a bá ní ìdààmú ọkàn. Tá a bá ń fi sọ́kàn pé gbogbo wa la máa ń ṣe ohun tó lè múnú bí àwọn míì, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa fara dà á fún ara wa. (Òwe 12:18; Ják. 3:​2, 5) Bákan náà, ẹ jẹ́ ká máa gbóríyìn fáwọn míì nítorí àwọn ànímọ́ dáadáa tí wọ́n ní.​—Éfé. 4:29. w19.02 11-12 ¶16-17

Tuesday, August 4

Jèhófà . . . ti fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in láti máa ṣe ìdájọ́ òdodo.​—Sm. 9:7.

Àwọn ìlànà kan wà nínú Òfin Mósè tó mú kó ṣòro láti fẹ̀sùn èké kan ẹnì kan pé ó hùwà ọ̀daràn. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn ní ẹ̀tọ́ láti ko ẹni tó fẹ̀sùn kàn án lójú. (Diu. 19:​16-19; 25:1) Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò lè dá ẹnì kan lẹ́bi àyàfi tí wọ́n bá rí ẹlẹ́rìí méjì tó jẹ́rìí sí i. (Diu. 17:6; 19:15) Tẹ́nì kan bá hùwà burúkú tó sì jẹ́ pé ẹnì kan péré ló jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà ńkọ́? Ẹni náà ò gbọ́dọ̀ ronú pé òun á mú un jẹ. Ó ṣe tán, Jèhófà rí ohun tó ṣe. Onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, ìgbà gbogbo ló sì máa ń ṣe ohun tó tọ́. Ó máa ń bù kún àwọn tó bá ń ṣègbọràn sí i, àmọ́ ó máa ń fìyà jẹ àwọn tó bá ṣi agbára wọn lò. (2 Sám. 22:​21-23; Ìsík. 9:​9, 10) Ó lè dà bíi pé àwọn kan hùwà burúkú, wọ́n sì mú un jẹ, àmọ́ tó bá tó àkókò lójú Jèhófà, gbogbo wọn ló máa fìyà jẹ. (Òwe 28:13) Tí wọn ò bá sì ronú pìwà dà, wọ́n á rí i pé “ohun tó ń bani lẹ́rù ló jẹ́ láti kó sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.”​—Héb. 10:​30, 31. w19.02 23-24 ¶20-21

Wednesday, August 5

Kò tíì sí wòlíì kankan ní Ísírẹ́lì bíi Mósè, ẹni tí Jèhófà mọ̀ lójúkojú.​—Diu. 34:10.

Gbogbo ìgbà ni Mósè máa ń wojú Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà. Kódà, Mósè “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Héb. 11:​24-27) Kò pé oṣù méjì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì ni ìṣòro ńlá kan jẹyọ, kódà wọn ò tíì dé Òkè Sínáì tí wàhálà náà fi ṣẹlẹ̀. Àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn pé kò sómi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè. Ọ̀rọ̀ yẹn le débi pé Mósè ké jáde sí Jèhófà pé: “Kí ni èmi yóò ti ṣe ti àwọn ènìyàn yìí sí? Ní ìgbà díẹ̀ sí i, wọn yóò sọ mí lókùúta!” (Ẹ́kís. 17:4) Jèhófà dá Mósè lóhùn, ó sì fún un ní ìtọ́ni tó ṣe kedere. Jèhófà sọ pé kó mú ọ̀pá rẹ̀, kó lu àpáta tó wà ní Hórébù, omi á sì jáde nínú rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Mósè ṣe bẹ́ẹ̀ ní ojú àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì.” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì mu omi débi tó tẹ́ wọn lọ́rùn, ìṣòro náà sì yanjú.​—Ẹ́kís. 17:​5, 6. w18.07 13 ¶4-5

Thursday, August 6

Ìfẹ́ ń gbéni ró.​—1 Kọ́r. 8:1.

Jèhófà ń lo ìjọ Kristẹni láti jẹ́ ká mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. Torí náà, àwa náà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nígbà tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti gbé wọn ró nípa tẹ̀mí, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ní ẹ̀dùn ọkàn. (1  Jòh. 4:​19-21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yin ró lẹ́nì kìíní-kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe ní tòótọ́.” (1 Tẹs. 5:11) Ìyẹn fi hàn pé gbogbo wa yálà a jẹ́ alàgbà tàbí a kì í ṣe alàgbà ló yẹ ká máa fara wé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù, ká sì máa tu àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nínú. (Róòmù 15:​1, 2) Nígbà míì, àwọn kan nínú ìjọ lè ní ìsoríkọ́ tó lékenkà, èyí sì lè gba pé kí wọ́n lọ rí dókítà. (Lúùkù 5:31) Ó yẹ káwọn alàgbà àtàwọn míì nínú ìjọ fi sọ́kàn pé àwọn kì í ṣe dókítà tó lè tọ́jú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì kí gbogbo wa ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ yálà a jẹ́ alàgbà tàbí a kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.”​—1 Tẹs. 5:14. w18.09 14 ¶10-11

Friday, August 7

Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ.​—Àìsá. 41:10.

Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà sí i làá túbọ̀ máa gbẹ́kẹ̀ lé e. Ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà mọ Jèhófà dáadáa ni pé ká máa fara balẹ̀ ka Bíbélì, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà. Inú Bíbélì la ti rí àkọsílẹ̀ bí Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà àtijọ́. Àwọn àkọsílẹ̀ yẹn mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa dáàbò bo àwa náà lónìí. Wòlíì Aísáyà sọ àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin kan ká lè mọ̀ pé lóòótọ́ ni Jèhófà ń dáàbò bò wá. Ó pe Jèhófà ní olùṣọ́ àgùntàn, ó sì fi àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà wé àgùntàn. Aísáyà sọ nípa Jèhófà pé: “Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀; oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí.” (Aísá. 40:11) Tá a bá nímọ̀lára pé Jèhófà ń fi ọwọ́ agbára rẹ̀ gbá wa mọ́ra, ọkàn wa máa balẹ̀ pé mìmì kan ò lè mì wá. Kí ọkàn rẹ lè balẹ̀ láìka àwọn ìṣòro tó ò ń kojú sí, ṣàṣàrò lórí ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Ó dájú pé á fún ẹ lókun kó o lè kojú àwọn ìṣòro tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. w19.01 7 ¶17-18

Saturday, August 8

Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run mi, ni inú mi dùn sí.​—Sm. 40:8.

Ǹjẹ́ o ní àwọn àfojúsùn èyíkéyìí nínú ìjọsìn Ọlọ́run? Bóyá ò ń sapá láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ó sì lè jẹ́ pé ṣe lò ń gbìyànjú láti sunwọ̀n sí i nínú bó o ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àti bó o ṣe ń dáhùn nípàdé. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá kíyè sí i pé ò ń tẹ̀ síwájú tàbí tí ẹnì kan bá gbóríyìn fún ẹ torí pé ò ń tẹ̀ síwájú? Ó dájú pé inú rẹ máa dùn, wàá sì láyọ̀ pé ọwọ́ rẹ ti ń tẹ àfojúsùn rẹ. Bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn torí pé ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o fi sípò àkọ́kọ́ láyé ẹ lò ń ṣe yẹn bíi ti Jésù. (Òwe 27:11) Téèyàn bá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó dájú pé á láyọ̀, ìgbésí ayé rẹ̀ á sì nítumọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58) Àmọ́ tó bá jẹ́ pé béèyàn ṣe máa rọ́wọ́ mú nínú ayé ló ń lé, kódà tó bá tiẹ̀ rí towó ṣe, asán ni gbogbo ẹ̀ máa já sí, òfo ọjọ́ kejì ọjà.​—Lúùkù 9:25. w18.12 22 ¶12-13

Sunday, August 9

Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé.​—Sm. 37:29.

Dáfídì ń tọ́ka sí ọjọ́ iwájú kan tí ìlànà Ọlọ́run á máa darí àwọn èèyàn tó ń gbé láyé. (2 Pét. 3:13) Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 65:22 sọ pé: “Bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí.” Èyí túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn á gbé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún láyé. Ìṣípayá 21:​1-4 sọ pé Ọlọ́run máa yí àfiyèsí rẹ̀ sọ́mọ aráyé, á sì bù kún wọn. Kódà, ọ̀kan lára àwọn ìlérí náà ni pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó máa wà nínú ayé tuntun ò ní kú mọ́ láé. Ádámù àti Éfà pàdánù Párádísè nínú ọgbà Édẹ́nì, àmọ́ ìrètí ṣì wà. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa bù kún aráyé lọ́jọ́ iwájú. Lábẹ́ ìmísí, Dáfídì sọ pé àwọn ọlọ́kàn tútù àtàwọn olódodo ló máa jogún ayé, wọ́n á sì gbé inú rẹ̀ títí láé. (Sm. 37:11) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé a ṣì máa gbádùn ara wa gan-an lọ́jọ́ iwájú. (Aísá. 11:​6-9; 35:​5-10; 65:​21-23) Ìgbà wo làwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀? Á ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìlérí tí Jésù ṣe fún ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ bá ṣẹ. (Lúùkù 23:43) Ìwọ náà lè wà nínú Párádísè yẹn. w18.12 7 ¶22-23

Monday, August 10

Ju gbogbo ohun mìíràn tí ò ń dáàbò bò, dáàbò bo ọkàn rẹ. ​—Òwe 4:23.

Ṣé a lè yẹra pátápátá fún èrò ayé? Kò ṣeé ṣe, inú ayé yìí làwa náà ń gbé, torí náà kò sí bá a ṣe lè yẹra pátápátá fún èrò wọn. (1 Kọ́r. 5:​9, 10) Bí àpẹẹrẹ, lóde ẹ̀rí a máa ń pàdé àwọn tó ń sọ ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Àmọ́ ti pé a ò lè yẹra pátápátá kò túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ fàyè gba àwọn èrò náà nínú ọkàn wa. Bíi ti Jésù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la gbọ́dọ̀ kọ èrò èyíkéyìí tó bá jẹ́ ti Sátánì. Yàtọ̀ síyẹn, a gbọ́dọ̀ dáàbò bo ọkàn wa, ká má ṣe fàyè gba èrò ayé. Ó yẹ ká fara balẹ̀ dáadáa ká tó yan àwọn tá a máa bá ṣọ̀rẹ́. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí kò sin Jèhófà, kò ní pẹ́ tá a fi máa bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi tiwọn, ó ṣe tán àwọn èèyàn máa ń sọ pé àgùntàn tó bá ń bá ajá rìn, á jẹ̀gbẹ́. (Òwe 13:20; 1 Kọ́r. 15:​12, 32, 33) Ó tún yẹ ká ṣọ́ra tó bá kan eré ìnàjú tá à ń wò. A gbọ́dọ̀ yẹra fún èyíkéyìí tó bá ń gbé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ìwà ipá àti ìṣekúṣe lárugẹ. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èrò tó “lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run” sọ ọkàn wa di ẹlẹ́gbin.​—2 Kọ́r. 10:5. w18.11 21 ¶16-17

Tuesday, August 11

Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ.​—Sm. 86:11.

Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ? Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa fi òtítọ́ kọ́ àwọn èèyàn. Nípa bẹ́ẹ̀, wàá di idà tẹ̀mí tí í ṣe “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” mú gírígírí. (Éfé. 6:17) Ó yẹ kí gbogbo wa sapá ká lè túbọ̀ jáfáfá nínú ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ni, ká sì fi “ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tím. 2:15) Bá a ṣe ń fi Bíbélì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ra òtítọ́ kí wọ́n sì fi ẹ̀kọ́ èké sílẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á túbọ̀ máa jinlẹ̀ lọ́kàn tiwa náà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, títí láé la ó máa rìn nínú òtítọ́. Ẹ̀bùn ńlá ni òtítọ́ tí Jèhófà fi jíǹkí wa. Ìdí ni pé ẹ̀bùn yìí ló jẹ́ ká ní ohun tó ṣeyebíye jù lọ láyé yìí, ìyẹn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Baba wa ọ̀run. Gbogbo ohun tá a mọ̀ báyìí ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tí Jèhófà ṣì máa kọ́ wa lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà ṣèlérí pé títí láé lòun á máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, mọyì òtítọ́ kó o sì jẹ́ kó ṣeyebíye sí ẹ bíi péálì àtàtà. Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti “ra òtítọ́, má sì tà á” láé.​—Òwe 23:23. w18.11 8 ¶2; 12 ¶15-17

Wednesday, August 12

Nóà [jẹ́] oníwàásù òdodo. ​—2 Pét. 2:5.

Ṣáájú Ìkún Omi, Nóà wàásù fáwọn èèyàn, ó sì dájú pé ó kìlọ̀ fún wọn nípa ìparun tó ń bọ̀. Jésù sọ pé: “Nítorí bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.” (Mát. 24:​38, 39) Láìka pé àwọn èèyàn ò kọbi ara sí ìwàásù rẹ̀, Nóà ò jẹ́ kó sú òun, ṣe ló ń bá a lọ láti máa kéde ìkìlọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn. Lónìí, à ń wàásù ìhìn rere káwọn èèyàn lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. Bíi ti Jèhófà, ó wù wá gan-an káwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run kí wọ́n lè “máa wà láàyè” nìṣó. (Ìsík. 18:23) Lẹ́sẹ̀ kan náà, bá a ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé àti níbi térò pọ̀ sí, ṣe là ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó pa ayé búburú yìí run.​—Ìsík. 3:​18, 19; Dán. 2:44; Ìfi. 14:​6, 7. w18.05 19 ¶8-9

Thursday, August 13

Ẹni tó ń fòótọ́ jẹ́rìí máa ń sọ òtítọ́.​—Òwe 12:17.

Ká sọ pé àwọn aláṣẹ fòfin de iṣẹ́ wa lágbègbè tó ò ń gbé, tí wọ́n sì ń béèrè ìsọfúnni nípa àwọn ará lọ́wọ́ rẹ, kí ló yẹ kó o ṣe? Ṣé gbogbo ohun tí wọ́n bá béèrè nípa àwọn ará ló yẹ kó o dáhùn? Kí ni Jésù ṣe nígbà tí gómìnà ará Róòmù ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò? Nígbà míì, Jésù kì í sọ ohunkóhun, ṣe ló máa ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníw. 3:​1, 7; Mát. 27:​11-14) Táwa náà bá wà nírú ipò bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká lo ìfòyemọ̀ ká má bàa kó àwọn ará wa sí wàhálà. (Òwe 10:19; 11:12) Ká sọ pé ọ̀rẹ́ ẹ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ kan dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tó o sì mọ̀ nípa rẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe? Ṣe ni kó o “sọ òtítọ́.” O gbọ́dọ̀ sọ gbogbo ohun tó o mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà fáwọn alàgbà, má sì da ojú ọ̀rọ̀ rú. Ìdí ni pé, ó yẹ káwọn alàgbà mọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.​—Ják. 5:​14, 15. w18.10 10 ¶17-18

Friday, August 14

Ẹ máa fún ara yín níṣìírí, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró.​—1 Tẹs. 5:11.

Báwo la ṣe lè fìfẹ́ gbé àwọn míì ró? Ọ̀nà kan ni pé ká máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn. (Ják. 1:19) Tá a bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sẹ́nì kan, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹni náà. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wà pẹ̀lú ẹnì kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn, a lè fọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè táá jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè gba tiẹ̀ rò, ká sì fìfẹ́ hàn sí i. Bákan náà, jẹ́ kó hàn lójú rẹ pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹ̀ sì ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Tí ẹni náà bá ń ṣàlàyé ohun tó ń ṣe é tàbí tó ń tú ọkàn rẹ̀ jáde, má ṣe dá ọ̀rọ̀ mọ ọ́n lẹ́nu, ńṣe ni kó o ṣe sùúrù títí táá fi bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ délẹ̀. Tó o bá fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, wàá túbọ̀ lóye bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ẹni náà máa fọkàn tán ẹ, á sì tẹ́tí sí àwọn ìmọ̀ràn tó o bá fún un torí pé ìwọ náà fara balẹ̀ tẹ́tí sí i nígbà tó ń sọ̀rọ̀. Tẹ́ni tó ní ẹ̀dùn ọkàn bá rí i pé lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ òun, ìyẹn á mú kára tù ú. w18.09 14 ¶10; 15 ¶13

Saturday, August 15

Ra òtítọ́.​—Òwe 23:23.

Ó máa ń náni ní ọ̀pọ̀ àkókò kéèyàn tó lè ra òtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè tẹ́tí sí ìhìn rere, kéèyàn ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde míì, kó sì tún máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Bó sì ṣe rí nìyẹn téèyàn bá máa múra ìpàdé sílẹ̀ kó sì máa pésẹ̀ sípàdé déédéé. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ‘ra àkókò’ pa dà tàbí ká yááfì àkókò tá à ń lò fáwọn nǹkan míì tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan. (Éfé. 5:​15, 16) Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kéèyàn tó lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì? Ọwọ́ kálukú nìyẹn wà. Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ nípa Jèhófà, àwámáridìí sì làwọn ọ̀nà rẹ̀, kódà títí ayé làá máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (Róòmù 11:33) Ẹ̀dà àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ fi òtítọ́ wé “òdòdó kékeré kan,” ó wá fi kún un pé: “Má ṣe jẹ́ kí òdòdó kan ṣoṣo nípa òtítọ́ tẹ́ ọ lọ́rùn. Tó bá jẹ́ pé ọ̀kan ti tó ni, a ò ní nílò àwọn míì mọ́. Túbọ̀ máa kó o jọ, kó o sì máa wá púpọ̀ sí i.” Bó ti wù ká pẹ́ láyé tó, àá ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Torí náà, ohun tó ṣe pàtàkì jù báyìí ni pé ká fọgbọ́n lo àkókò wa ká lè kọ́ gbogbo ohun tá a bá lè mọ̀ nípa Jèhófà lásìkò tá a wà yìí. w18.11 4 ¶7

Sunday, August 16

Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín. ​—Éfé. 5:25.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé kí àwọn ọkọ máa bá àwọn aya “wọn gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀,” ìyẹn ni pé kí wọ́n máa gba tiwọn rò, kí wọ́n sì lóye bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn. (1 Pét. 3:7) Bí àpẹẹrẹ, ọkọ tó lóye aya rẹ̀ máa gbà pé olùrànlọ́wọ́ ni ìyàwó òun jẹ́ àti pé àwọn yàtọ̀ síra láwọn ọ̀nà kan, síbẹ̀ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ipò tó rẹlẹ̀ làwọn obìnrin wà. (Jẹ́n. 2:18) Torí náà, irú ọkọ bẹ́ẹ̀ á máa gba ti aya rẹ̀ rò, á máa buyì kún un, á sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Ọkọ tó bá ń gba ti aya rẹ̀ rò á máa kíyè sára tó bá wà pẹ̀lú àwọn obìnrin míì. Bí àpẹẹrẹ, kò ní máa bá àwọn obìnrin míì tage tàbí kó máa ṣe bí ẹni tó gba tiwọn. Irú ọkọ bẹ́ẹ̀ kì í bá àwọn obìnrin míì dọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀ lórí ìkànnì àjọlò tàbí lórí àwọn ìkànnì míì. (Jóòbù 31:1) Dípò bẹ́ẹ̀, á jẹ́ olóòótọ́ sí aya rẹ̀ kì í ṣe torí pé ó nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nìkan, àmọ́ tórí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì kórìíra ohun tó burú.​—Sm. 19:14; 97:10. w18.09 29 ¶3-4

Monday, August 17

Ẹni tó bá hùwà bí ẹni tó kéré láàárín gbogbo yín ni ẹni tó tóbi. ​—Lúùkù 9:48.

Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro láti fi àwọn ohun tá a kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò? Ìdí kan ni pé, ó gba ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kéèyàn tó lè ṣe ohun tó tọ́. Kò rọrùn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí torí pé àwọn “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera” àti “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu” ló yí wa ká. (2 Tím. 3:​1-3) Torí pé a jẹ́ èèyàn Ọlọ́run, a mọ̀ pé àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ò dáa. Ṣùgbọ́n, ó jọ pé àwọn tó ń hu àwọn ìwà yìí gan-an ló ń gbádùn ayé wọn, tá ò bá sì ṣọ́ra a lè bẹ̀rẹ̀ sí í jowú wọn. (Sm. 37:1; 73:3) A lè máa ronú pé: ‘Ṣé àǹfààní tiẹ̀ wà nínú kéèyàn máa fi ire àwọn míì ṣáájú tara ẹ̀? Ṣé àwọn èèyàn ò ní máa fojú pa mí rẹ́ tí mo bá ń ṣe bí “ẹni tí ó kéré jù”?’ Tá a bá jẹ́ kí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tó kúnnú ayé yìí kéèràn ràn wá, àjọṣe àwa àtàwọn ará ìjọ lè má gún régé mọ́, ó sì lè ṣòro fáwọn èèyàn láti mọ̀ pé Kristẹni ni wá. Kíyẹn má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa, á dáa ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà nínú Bíbélì, ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. w18.09 3 ¶1

Tuesday, August 18

Ayọ̀ . . . wà nínú fífúnni. ​—Ìṣe 20:35.

Kí Jèhófà tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan, òun nìkan ló dá wà. Síbẹ̀ Jèhófà ò ro tara ẹ̀ nìkan lásìkò yìí, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fi ìwàláàyè jíǹkí àwọn ẹ̀dá tó wà lọ́run àti láyé. “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà, ó sì ń fún gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní ohun rere. (1 Tím. 1:11; Ják. 1:17) Jèhófà jẹ́ kó ṣe kedere pé táwa náà bá fẹ́ láyọ̀, àfi ká jẹ́ ọ̀làwọ́, ká sì máa fún àwọn míì ní nǹkan. (Róòmù 1:20) Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́n. 1:27) Ìyẹn ni pé Ọlọ́run dá wa lọ́nà tá a fi máa gbé àwọn ànímọ́ rẹ̀ yọ. Tá a bá fẹ́ láyọ̀ kí ìgbésí ayé wa sì nítumọ̀, a gbọ́dọ̀ máa fara wé Jèhófà, ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ wá lọ́kàn, ká sì máa fúnni látọkàn wá. (Fílí. 2:​3, 4; Ják. 1:5) Kí nìdí? Ìdí ni pé bí Jèhófà ṣe dá wa nìyẹn. Láìka àìpé wa sí, a lè fara wé Jèhófà, ká sì jẹ́ ọ̀làwọ́. Jèhófà fẹ́ ká máa fara wé òun, inú rẹ̀ sì máa ń dùn tó bá rí i pé a jẹ́ ọ̀làwọ́.​—Éfé. 5:1. w18.08 18 ¶1-2; 19 ¶4

Wednesday, August 19

Àwọn àgùntàn mi máa ń fetí sí ohùn mi.​—Jòh. 10:27.

Kì í ṣe pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń fetí sí ohùn rẹ̀ nìkan ni, wọ́n tún ń fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò. Wọn kì í jẹ́ kí “àníyàn ìgbésí ayé” gbà wọ́n lọ́kàn. (Lúùkù 21:34) Kàkà bẹ́ẹ̀, bí wọ́n ṣe máa pa àṣẹ Jésù mọ́ ló jẹ wọ́n lógún kódà lásìkò tí nǹkan nira. Wọ́n gbà pé bíná ń jó bíjì ń jà, ìfẹ́ Jèhófà làwọn máa ṣe. Ohun míì tá a lè ṣe láti fi hàn pé à ń fetí sí Jésù ni pé ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń múpò iwájú. (Héb. 13:​7, 17) Onírúurú àtúnṣe ni ètò Ọlọ́run ti ṣe láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣàtúnṣe sí àwọn ohun tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àtọ̀nà tá à ń gbà wàásù. Bákan náà, wọ́n ṣàtúnṣe sí bá a ṣe ń ṣe ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀, ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa àti bá a ṣe ń bójú tó wọn. A mà dúpẹ́ o fún àwọn ìtọ́ni tó bọ́gbọ́n mu tó sì fìfẹ́ hàn yẹn! Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wa gan-an tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ètò rẹ̀ ń fún wa. w19.03 10-11 ¶11-12

Thursday, August 20

Kò yẹ ká jẹ́ ọmọdé mọ́, tí à ń . . . gbá síbí sọ́hùn-ún nípasẹ̀ ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí a fi hùmọ̀ ẹ̀tàn.​—Éfé. 4:14.

Tí ìsọfúnni kan kò bá ti jẹ́ òótọ́ délẹ̀délẹ̀, irọ́ ni, ó sì lè ṣini lọ́nà. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé lápá ìwọ̀ oòrùn Odò Jọ́dánì nígbà ayé Jóṣúà. (Jóṣ. 22:​9-34) Wọ́n gbọ́ pé àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì àti Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè tó ń gbé ní apá ìlà oòrùn mọ pẹpẹ ràgàjì kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ ni pé wọ́n mọ pẹpẹ kan, síbẹ̀ wọn ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìdí tí wọ́n fi mọ pẹpẹ náà. Ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn rò ni pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé lápá ìlà oòrùn ti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. (Jóṣ. 22:​9-12) Àmọ́ kí wọ́n tó kógun lọ, wọ́n ṣe ohun kan tó dáa. Wọ́n rán àwọn ọkùnrin tó ṣeé fọkàn tán pé kí wọ́n lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà wò. Kí wá ni wọ́n bá bọ̀? Wọ́n rí i pé kì í ṣe torí kí wọ́n lè máa bọ̀rìṣà ni wọ́n ṣe mọ pẹpẹ yẹn, àmọ́ wọ́n mọ ọ́n kó lè wà fún ìrántí. Èyí á jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ lẹ́yìnwá ọ̀la pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni wọ́n. Ó dájú pé inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn máa dùn pé àwọn wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa kí wọ́n tó gbé ìgbésẹ̀. Ká sọ pé wọ́n ti kógun ja àwọn arákùnrin wọn ni, ìpakúpa tó máa wáyé ò bá bùáyà! w18.08 5 ¶9-10

Friday, August 21

Kí ẹni tó bá rò pé òun dúró kíyè sára kó má bàa ṣubú.​—1 Kọ́r.10:12.

Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tó ń sin Jèhófà lè bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sí ìwà burúkú tí wọn ò bá ṣọ́ra. Ẹni tó lọ́wọ́ sí ìwà burúkú lè máa ronú pé òun ṣì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Àmọ́ ká fi sọ́kàn pé, ó lè máa wu ẹnì kan láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà tàbí kó ronú pé òun jẹ́ adúróṣinṣin, síbẹ̀ kí inú Jèhófà má dùn sẹ́ni náà. (1 Kọ́r. 10:​1-5) Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń ṣàníyàn torí pé Mósè pẹ́ lórí Òkè Sínáì, àwa Kristẹni lónìí náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn pé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ti ń pẹ́ jù, ká sì máa ronú pé ìgbà wo ni ayé tuntun máa dé. Ó lè jọ pé àwọn ìlérí Jèhófà ti ń pẹ́ jù lójú wa tàbí pé wọ́n dà bí àlá tí kò lè ṣẹ. Tá ò bá tún èrò wa ṣe, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn nǹkan tara, ká sì pa ìjọsìn Jèhófà tì. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àá fi Jèhófà sílẹ̀, àá sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sáwọn ìwà burúkú tá ò lérò pé a lè lọ́wọ́ sí tẹ́lẹ̀. w18.07 21 ¶17-18

Saturday, August 22

Màá tún ṣe ohun tí o ní kí n ṣe yìí, torí o ti rí ojúure mi, mo sì fi orúkọ mọ̀ ọ́.​—Ẹ́kís. 33:17.

Ó dájú pé Jèhófà lè mọ àwa náà, kó sì bù kún wa. Àmọ́, kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Jèhófà tó lè mọ̀ wá? A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká sì ya ara wa sí mímọ́ fún un. (1  Kọ́r. 8:3) Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe àwa àti Baba wa ọ̀run jẹ́. Bíi tàwọn Kristẹni tó wà ní Gálátíà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí, kò yẹ káwa náà pa dà sídìí “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ aláìlera àti akúrẹtẹ̀” tó wà nínú ayé yìí. (Gál. 4:9) Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní yìí ti tẹ̀ síwájú gan-an débi pé wọ́n ti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni yìí kan náà ti ń “padà sẹ́yìn” sí àwọn nǹkan tí kò ní láárí. Ṣe ló dà bí ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ fún wọn pé: “Ládúrú ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ ti kọ́, kí ló dé tó jẹ́ pé àwọn nǹkan tí kò wúlò tẹ́ ẹ ti fi sílẹ̀ lẹ tún wá ń ṣe?” w18.07 8 ¶5-6

Sunday, August 23

Ọlọ́gbọ́n máa ń fetí sílẹ̀, á sì kọ́ ẹ̀kọ́ sí i.​—Òwe 1:5.

Kò dìgbà táwa fúnra wa bá jìyà ká tó mọ̀ pé àbámọ̀ ló máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀ téèyàn bá rú òfin Ọlọ́run. A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn, ó ṣe tán, wọ́n ní àgbà tó jìn sí kòtò, ó kọ́ ará yòókù lọ́gbọ́n. Ọ̀dọ̀ Jèhófà la ti lè rí ìtọ́ni tó dáa jù lọ, a sì lè rí àwọn ìtọ́ni yìí tá a bá ń ka àwọn ìtàn inú Bíbélì, tá a sì ń ronú lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ìyà tí Ọba Dáfídì jẹ àti ẹ̀dùn ọkàn tó ní lẹ́yìn tó rú òfin Jèhófà tó sì ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà. (2 Sám. 12:​7-14) Bá a ṣe ń ronú lórí ìtàn yìí, a lè bi ara wa pé: ‘Kí ló yẹ kí Ọba Dáfídì ti ṣe kó má bàa kó sínú wàhálà yìí? Témi náà bá kojú irú àdánwò yìí, kí ni màá ṣe? Ṣé màá ṣe bíi Jósẹ́fù kí n sì sá fún ẹ̀ṣẹ̀, àbí màá ṣe bíi ti Dáfídì?’ (Jẹ́n. 39:​11-15) Tá a bá ń ronú lórí àbámọ̀ tó máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀ṣẹ̀, á jẹ́ kí ìpinnu wa láti “kórìíra ohun búburú” túbọ̀ lágbára.​—Ámósì 5:15. w18.06 17 ¶5, 7

Monday, August 24

Ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì, àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.​—Mát. 22:21.

Ìwà ìrẹ́jẹ ló sábà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Nígbà ayé Jésù, ọ̀rọ̀ sísan owó orí máa ń dá wàhálà sílẹ̀ lágbo òṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, ìjọba Róòmù ní káwọn èèyàn forúkọ sílẹ̀ kí wọ́n lè rí i dájú pé wọ́n ń san owó orí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan làwọn tó wà lábẹ́ àkóso Róòmù ń san owó orí fún nígbà yẹn tó fi mọ́ ẹrù, ilé àti ilẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́ o, oníjẹkújẹ làwọn agbowó orí torí pé owó gegere ni wọ́n ń bù lé àwọn èèyàn. Ìwà wọn burú débi pé ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lówó kí wọ́n lè fi wọ́n sí ipò kan tí wọ́n á ti rówó rẹpẹtẹ. Àpẹẹrẹ kan ni Sákéù tó jẹ́ olórí agbowó orí ní Jẹ́ríkò, owó tó ń fipá gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn ló sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀. (Lúùkù 19:​2, 8) Ohun tí ọ̀pọ̀ wọn sì máa ń ṣe nìyẹn. Àwọn ọ̀tá Jésù ń wá ọ̀nà láti dẹkùn mú un, wọ́n bi í bóyá ó yẹ káwọn Júù máa san “owó orí,” ìyẹn dínárì kan tí ìjọba Róòmù ń béèrè. (Mát. 22:​16-18) Àwọn Júù kì í fẹ́ san owó orí yìí torí ó máa ń rán wọn létí pé abẹ́ ìjọba Róòmù ni wọ́n wà. w18.06 5-6 ¶8-10

Tuesday, August 25

Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.​—Gál. 6:7.

Tẹ́nì kan bá yàn láti tẹ̀ lé Sátánì, ohun tí Sátánì máa fún un kò ní tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìyà tó máa jẹ. (Jóòbù 21:​7-17; Gál. 6:8) Àǹfààní wo ló wà nínú bá a ṣe mọ̀ pé Sátánì ló ń darí ayé? Ó ń jẹ́ ká fi àwọn ìjọba èèyàn sí àyè tó yẹ wọ́n, ó sì ń jẹ́ ká máa fìtara kìlọ̀ fáwọn èèyàn. Jèhófà fẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ. (1 Pét. 2:17) Ó sì tún fẹ́ ká máa ṣègbọràn sí òfin wọn tí kò bá ti ta ko àwọn ìlànà rẹ̀. (Róòmù 13:​1-4) Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, a ò gbọ́dọ̀ gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú èyíkéyìí tàbí ká máa gbé alákòóso kan lárugẹ. (Jòh. 17:​15, 16; 18:36) Bákan náà, Sátánì ò fẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run, ó sì ń bà á lórúkọ jẹ́, ìdí nìyẹn tá a fi ń sapá láti kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Inú wa máa ń dùn pé à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, a sì ń lo orúkọ rẹ̀ torí a mọ̀ pé, tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àǹfààní tá a máa rí á ju àǹfààní èyíkéyìí tí owó tàbí nǹkan tara lè fún wa.​—Aísá. 43:10; 1 Tím. 6:​6-10. w18.05 24 ¶8-9

Wednesday, August 26

Kí aya má ṣe kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀.​—1 Kọ́r. 7:10.

Ká sọ pé ìṣòro yọjú nínú ìdílé, ṣé ohun tó kàn ni pé kí wọ́n pínyà? Bíbélì ò sọ onírúurú nǹkan tó lè fa ìpínyà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Tí obìnrin kan bá ní ọkọ tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí ọkùnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.’ (1 Kọ́r. 7:​12, 13) Ìlànà yìí kan náà là ń tẹ̀ lé lónìí. Síbẹ̀, àwọn ipò kan wà tó jẹ́ pé “ọkọ tí kò gbà gbọ́” lè máa ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé kò ṣeé bá gbé. Ó lè máa lu ìyàwó rẹ̀ nílùkulù débi tí ìyàwó náà fi gbà pé ọkọ òun lè ṣe òun léṣe tàbí kó gbẹ̀mí òun. Ó lè kọ̀ láti pèsè fún ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ tàbí kó mú kó ṣòro fún un gan-an láti sin Jèhófà. Nírú àwọn ipò yìí, àwọn Kristẹni kan ti pinnu pé àwọn á pínyà, wọ́n gbà pé onítọ̀hún kò ṣeé bá gbé láìka ohun yòówù kó sọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, a ráwọn Kristẹni míì tí wọ́n níṣòro tó le gan-an, síbẹ̀ tí wọ́n ń fara dà á, tí wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí ìgbéyàwó wọn má bàa dà rú. w18.12 13 ¶14, 16; 14 ¶17

Thursday, August 27

Àwọn yìí ló . . . ń fi ìfaradà so èso.​—Lúùkù 8:15.

Nínú àpèjúwe afúnrúgbìn tó wà ní Lúùkù 8:​5-8, 11-15, irúgbìn náà dúró fún “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tàbí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Erùpẹ̀ dúró fún ọkàn àwọn èèyàn. Irúgbìn tó bọ́ sórí erùpẹ̀ àtàtà náà fìdí múlẹ̀, ó rú jáde, ó sì dàgbà di igi àlìkámà. Lẹ́yìn náà, “ó mú èso jáde ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún.” Nígbà táwọn òbí wa tàbí Kristẹni míì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n gbin irúgbìn náà sórí erùpẹ̀ àtàtà. Inú wọn dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí i pé à ń tẹ̀ síwájú. Ṣe ni irúgbìn náà bẹ̀rẹ̀ sí í fìdí múlẹ̀ lọ́kàn wa, ó sì dàgbà títí tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í so èso. Bíi ti igi àlìkámà tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan, igi àlìkámà kì í mú igi àlìkámà míì jáde, bí kò ṣe hóró tàbí irúgbìn míì. Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tiwa náà rí, a kì í mú ọmọlẹ́yìn tuntun jáde, kàkà bẹ́ẹ̀ irúgbìn òtítọ́ là ń mú jáde. Báwo la ṣe ń mú irúgbìn míì jáde? Gbogbo ìgbà tá a bá ti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ṣe là ń fọ́n irúgbìn tí wọ́n gbìn sọ́kàn wa. (Lúùkù 6:45; 8:1) Torí náà, àpèjúwe yìí jẹ́ ká rí i pé tá a bá ń wàásù ìhìn rere náà láìjẹ́ kó sú wa, à ń “so èso pẹ̀lú ìfaradà” nìyẹn. w18.05 14 ¶10-11

Friday, August 28

Gbogbo àwọn tí mo fẹ́ràn ni mò ń bá wí, tí mo sì ń tọ́ sọ́nà. ​—Ìfi. 3:19.

Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù kàn ń fún àwọn ará níṣìírí nìkan ni, ó tún lo ara rẹ̀ fún wọn, kódà ó sọ pé “a ó sì ná mi tán pátápátá fún” yín. (2 Kọ́r. 12:15) Lọ́nà kan náà, kò yẹ kó jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan làwọn alàgbà á fi máa fún àwọn ará níṣìírí, ó tún yẹ kọ́rọ̀ àwọn ará máa jẹ wọ́n lọ́kàn, kí wọ́n sì máa ṣe ohun tó fi hàn bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́r. 14:3) Àwọn ìgbà míì wà tó yẹ káwọn alàgbà báni wí. Àmọ́ tí wọ́n bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó ń gbéni ró, ó yẹ kí wọ́n máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó báni wí nínú Bíbélì. Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn tó jíǹde. Ó bá àwọn ìjọ kan wí ní Éṣíà Kékeré, àmọ́ kó tó ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kíyè sí ohun tó ṣe. Ó kọ́kọ́ gbóríyìn fún àwọn ìjọ tó wà ní Éfésù, Págámù àti Tíátírà. (Ìṣí. 2:​1-5, 12, 13, 18, 19) Ó yẹ káwọn alàgbà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tí wọ́n bá fẹ́ báni wí. w18.04 22 ¶8-9

Saturday, August 29

Ẹ̀yin bàbá, . . . ẹ máa tọ́ [àwọn ọmọ yín] dàgbà nínú ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.​—Éfé. 6:4.

Ẹ̀yin òbí, kò sí àní-àní pé ẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe kí àwọn ọmọ yín má bàa kó àrùn. Fún ìdí yìí, ẹ máa ń tọ́jú ilé yín dáadáa, tí ohunkóhun bá sì wà tó lè mú kí ẹ̀yin tàbí àwọn ọmọ yín ṣàìsàn, ó dájú pé ṣe lẹ máa ń kó wọn dànù. Lọ́nà kan náà, ó yẹ kẹ́ ẹ dáàbò bo àwọn ọmọ yín, kí àwọn fíìmù, ètò orí tẹlifíṣọ̀n, àwọn géèmù àtàwọn ìkànnì ayé má bàa gbin èrò Sátánì sí wọn lọ́kàn. Ẹ̀yin ni Jèhófà gbéṣẹ́ fún láti bójú tó àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì kọ́ wọn ní ìlànà rẹ̀. (Òwe 1:8) Torí náà, ẹ jẹ́ káwọn ọmọ yín mọ àwọn òfin tí wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé, ìyẹn àwọn òfin tó bá ìlànà Bíbélì mu. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ irú fíìmù tí wọ́n lè wò àtèyí tí wọn ò gbọ́dọ̀ wò, kẹ́ ẹ sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tẹ́ ẹ fi sọ bẹ́ẹ̀. (Mát. 5:37) Báwọn ọmọ yín ṣe ń dàgbà, ẹ kọ́ wọn kí wọ́n lè mọ béèyàn ṣe ń fi ìlànà Jèhófà pinnu ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. (Héb. 5:14) Bó ti wù kó rí, ẹ fi sọ́kàn pé wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ lára yín.​—Diu. 6:​6, 7; Róòmù 2:21. w19.01 16 ¶8

Sunday, August 30

Ẹ̀yin àgbà ọkùnrin àti ẹ̀yin ọ̀dọ́. Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà. ​—Sm. 148:​12, 13.

Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, o ò ṣe sún mọ́ àwọn àgbàlagbà, wọ́n ní ọmọdé tó bá mọ ọwọ́ wẹ̀ á bá àgbà jẹun. O lè ní kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà fún ẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìrírí wọn máa fún ẹ lókun, àwọn náà á sì jàǹfààní lára ẹ. Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa kí àwọn ẹni tuntun tó bá wá sípàdé káàbọ̀. Tó o bá darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, o lè ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ṣé àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tó rọrùn fún wọn lo pín wọn sí? Láwọn ìgbà míì, á dáa kó o pín àwọn ọ̀dọ́ mọ́ wọn kí wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́ lóde ẹ̀rí. Bákan náà, ó yẹ kó o fi ìgbatẹnirò hàn sí àwọn aláìlera àtàwọn tí ipò wọn ò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kí tèwetàgbà máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.​—Léf. 19:32. w18.06 23-24 ¶10-12

Monday, August 31

Ẹ má . . . fi òmìnira yín bojú láti máa hùwà burúkú, àmọ́ kí ẹ lò ó bí ẹrú Ọlọ́run.​—1 Pét. 2:16.

Ó yẹ káwa náà mọyì bí Jèhófà ṣe dá wa nídè lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ká sì máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó. (Sm. 40:8) Ó yẹ ká mọyì òmìnira tá a ní, àmọ́ ó tún yẹ ká kíyè sára ká má lọ ṣi òmìnira náà lò. Àpọ́sítélì Pétérù kìlọ̀ pé ká má ṣe lo òmìnira wa bíi bojúbojú láti lé àwọn nǹkan tara. Ǹjẹ́ ìkìlọ̀ yẹn ò rán wa létí ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù? Ká fi sọ́kàn pé àsìkò tiwa yìí burú ju tiwọn lọ, tá ò bá sì ṣọ́ra, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà. Bí àpẹẹrẹ, onírúurú nǹkan ni ayé Sátánì fi ń tan àwọn èèyàn jẹ, bí aṣọ, ìmúra, oúnjẹ, ohun mímu, eré ìnàjú, ìgbafẹ́ àtàwọn nǹkan míì. Àwọn tó ń polówó ọjà máa ń lo àwọn tó rẹwà kí wọ́n lè fọgbọ́n tan àwọn èèyàn láti ra ohun tí wọn ò nílò. Ẹ ò rí i pé tá ò bá ṣọ́ra, ó rọrùn gan-an láti ṣi òmìnira wa lò. w18.04 10 ¶7-8

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́