September
Tuesday, September 1
Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. —1 Pét. 1:8.
Jésù fi hàn pé òun mọ bí nǹkan ṣe rí lára Màtá àti Màríà. Nígbà tí Jésù rí bí wọ́n ṣe ń ṣọ̀fọ̀ Lásárù arákùnrin wọn tó kú, ṣe ló “bẹ̀rẹ̀ sí í da omi lójú.” (Jòh. 11:32-35) Kì í ṣe torí pé ó ń ṣàárò ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló ṣe ń sunkún. Ó ṣe tán, ó mọ̀ pé òun máa jí i dìde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìdí tí Jésù fi sunkún ni pé ó mọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe dun Màtá àti Màríà tó. Inú wa dùn gan-an bá a ṣe mọ̀ pé Jésù máa ń bá àwọn èèyàn kẹ́dùn torí ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í ṣe ẹni pípé bíi Jésù, síbẹ̀ a mọyì bó ṣe fìfẹ́ bá àwọn míì lò. Inú wa dùn pé òun ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ti ń ṣàkóso báyìí. Láìpẹ́, ó máa fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé. Torí pé Jésù ti gbé lórí ilẹ̀ ayé rí tó sì ti fara da onírúurú ìṣòro, òun ló wà ní ipò tó dáa jù láti gba aráyé là kúrò nínú wàhálà tí Sátánì dà sí wa lágbada. A mà dúpẹ́ o pé a ní Ọba tó “lè bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.”—Héb. 2:17, 18; 4:15, 16. w19.03 17 ¶12-13
Wednesday, September 2
Kò sí èèyàn tó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba tó rán mi fà á.—Jòh. 6:44.
Ká fi sọ́kàn pé àwa kọ́ la máa pinnu bóyá ẹnì kan máa wá sínú òtítọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. A lè ṣe ipa tiwa láti kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, àmọ́ Jèhófà ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù. (1 Kọ́r. 3:6, 7) Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fa àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Láìka gbogbo ìsapá wa, ohun tó wà lọ́kàn kálukú ló máa pinnu bóyá ó máa sin Jèhófà tàbí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 13:4-8) Ká má gbàgbé pé Jésù ni Olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ jù, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ni kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Torí náà, kò yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn tá à ń wàásù fún bá kọtí ikún sọ́rọ̀ wa. Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú ká máa gba tàwọn èèyàn rò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Lára ẹ̀ ni pé àwa fúnra wa máa túbọ̀ gbádùn iṣẹ́ náà, àá sì rí ayọ̀ tó wà nínú fífúnni. Yàtọ̀ síyẹn, á túbọ̀ rọrùn fáwọn “olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Ìṣe 13:48) Torí náà, “nígbà tí a bá ti láǹfààní rẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa ṣe rere fún gbogbo èèyàn.” (Gál. 6:10) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa láyọ̀ bá a ṣe ń mú ìyìn bá Jèhófà Baba wa ọ̀run.—Mát. 5:16. w19.03 25 ¶18-19
Thursday, September 3
Màá . . . yìn ọ́ láàárín ìjọ. —Sm. 22:22.
Ọba Dáfídì sọ pé: “Jèhófà tóbi, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi.” (Sm. 145:3) Dáfídì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìyẹn sì mú kó máa yin Ọlọ́run “ní àárín ìjọ.” (1 Kíró. 29:10-13; Sm. 40:5) Ọ̀nà pàtàkì kan tá à ń gbà yin Jèhófà lónìí ni bá a ṣe ń dáhùn nípàdé. Inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń gbọ́ onírúurú ìdáhùn nípàdé. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọdé kan bá dáhùn látọkàn wá, orí wa máa ń wú. Tí ẹnì kan bá ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i tàbí ohun kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀, ó máa ń wọ̀ wá lọ́kàn gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń wú wa lórí tí àwọn tó ń kọ́ èdè wa tàbí àwọn tó ń tijú bá dáhùn nípàdé. (1 Tẹs. 2:2) Kí la lè ṣe táá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọrírì ìsapá wọn? Ó yẹ ká máa gbóríyìn fún wọn lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí. Ohun míì tá a lè ṣe ni pé kí àwa fúnra wa máa dáhùn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, bá a ṣe ń fún àwọn míì níṣìírí làwa náà á máa rí ìṣírí gbà.—Róòmù 1:11, 12. w19.01 8 ¶1-2; 9 ¶6
Friday, September 4
Ẹ máa dúpẹ́.—Kól. 3:15.
Àwọn ọkùnrin mẹ́wàá kan wà tí wọ́n jẹ́ adẹ́tẹ̀. Wọ́n ń wá ìwòsàn lójú méjèèjì, àmọ́ kò jọ pé wọ́n á rí ẹni ràn wọ́n lọ́wọ́. Lọ́jọ́ kan, wọ́n rí Jésù Olùkọ́ Ńlá náà látọ̀ọ́kán. Wọ́n ti gbọ́ pé onírúurú àìsàn ni Jésù máa ń wò. Wọ́n wá kígbe pé: “Jésù, Olùkọ́ni, ṣàánú fún wa!” Bí wọ́n ṣe rí ìwòsàn gbà nìyẹn o. Kò sí àní-àní pé gbogbo wọn ló mọyì ohun tí Jésù ṣe fún wọn. Àmọ́, ẹnì kan ṣoṣo péré ló pà dá wá dúpẹ́ oore tí Jésù ṣe fún un. Ó ṣe kedere pé kì í wulẹ̀ ṣe pé ará Samáríà yẹn moore nìkan, kódà ó “fi ohùn rara” yin Ọlọ́run lógo. (Lúùkù 17:12-19) Bíi ti ará Samáríà yẹn, ó máa ń wù wá pé ká dúpẹ́ oore táwọn èèyàn ṣe fún wa. Tó bá di pé ká fẹ̀mí ìmoore hàn, kò sí ẹlẹ́gbẹ́ Jèhófà. Àbí, kí nìdí tí Jèhófà fi ń bù kún àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀? Kò sí àní-àní, torí pé ó mọyì ohun tí wọ́n ṣe ni. (2 Sám. 22:21; Sm. 13:6; Mát. 10:40, 41) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbà wá níyànjú pé ká “máa fara wé Ọlọ́run, bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ.” (Éfé. 5:1) Torí náà, ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ oore ni pé a fẹ́ fara wé Jèhófà. w19.02 14 ¶1-2; 15 ¶4
Saturday, September 5
Mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀! —Jóòbù 27:5.
Ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ ọmọléèwé fìrẹ̀lẹ̀ sọ fún olùkọ́ àti àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ pé òun ò ní lọ́wọ́ sí ayẹyẹ kan tí kò bá Bíbélì mu. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó máa ń tijú gan-an ń wàásù láti ilé dé ilé, ó kíyè sí i pé ọmọléèwé rẹ̀ kan tó máa ń fi àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yẹ̀yẹ́ ló ń gbé nílé tó kàn. Ọ̀gá baálé ilé kan tí kì í fiṣẹ́ ṣeré sọ fún un pé kó ṣe ohun kan tí kò tọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ tí kò bá ṣe ohun tí ọ̀gá náà sọ, síbẹ̀ ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé òun ò ní ṣe é torí pé inú Ọlọ́run ò dùn sí ìwà bẹ́ẹ̀. (Róòmù 13:1-4; Héb. 13:18) Ànímọ́ wo ni wàá sọ pé àwọn ará yẹn ní? Ó ṣeé ṣe kó o kíyè sí i pé wọ́n jẹ́ onígboyà àti olóòótọ́. Àmọ́ ohun kan ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ìyẹn sì ni pé wọn ò fi àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà ṣeré, wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló fi hàn pé ìlànà Jèhófà làwọn ń tẹ̀ lé. Kò sí àní-àní pé ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Jèhófà ló mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì dájú pé inú Jèhófà dùn sí wọn gan-an, kódà àmúyangàn ni wọ́n jẹ́ fún un. Àwa náà máa fẹ́ jẹ́ àmúyangàn fún Jèhófà. w19.02 2 ¶1-2
Sunday, September 6
Òfin ní òjìji àwọn nǹkan rere tó ń bọ̀.—Héb. 10:1.
Òfin Mósè dìídì dáàbò bo àwọn tí kò lè dáàbò bo ara wọn, àwọn bí ọmọ tí kò ní òbí, opó àtàwọn àjèjì. Jèhófà sọ fún àwọn onídàájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì pé: “O ò gbọ́dọ̀ ṣe èrú tí o bá ń dá ẹjọ́ àjèjì tàbí ọmọ aláìníbaba, o ò sì gbọ́dọ̀ gba aṣọ opó láti fi ṣe ìdúró.” (Diu. 24:17) Jèhófà kò fọ̀rọ̀ àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ ṣeré rárá, kódà ọ̀rọ̀ wọn jẹ ẹ́ lógún gan-an. Á sì fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá fojú pọ́n wọn. (Ẹ́kís. 22:22-24) Jèhófà fẹ́ káwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. Ó kórìíra ìfipábánilòpọ̀, bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe àtàwọn ìṣekúṣe míì. Ó fẹ́ káwọn tó ń múpò iwájú dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, ní pàtàkì jù lọ àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́, kí wọ́n sì rí i pé wọ́n rí ìdájọ́ òdodo gbà. (Léf. 18:6-30) Tó bá dá wa lójú pé ọ̀nà tó tọ́ ni Jèhófà ń gbà bá wa lò, ìfẹ́ tá a ní fún un á túbọ̀ jinlẹ̀. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tá a sì mọyì àwọn ìlànà òdodo rẹ̀, ìyẹn á mú ká nífẹ̀ẹ́ àwọn míì ká sì máa finú kan bá wọn lò. w19.02 24-25 ¶22-26
Monday, September 7
Kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ ayé sílẹ̀.—Títù 2:12.
Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa kí Sátánì má bàa sọ èrò wa dìbàjẹ́. Jèhófà ti kọ́ wa pé ‘kí a má ṣe mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ èyíkéyìí láàárín wa.’ (Éfé. 5:3) Àmọ́, kí la máa ṣe tí àwọn ọmọ ilé ìwé wa tàbí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ bá dá ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe sílẹ̀? Ẹ̀rí ọkàn wa tó dà bí ẹ̀ṣọ́ lè bẹ̀rẹ̀ sí í kìlọ̀ fún wa. (Róòmù 2:15) Ìbéèrè náà ni pé ṣé a máa tẹ́tí sí i? Ó lè ṣe wá bíi pé ká tẹ́tí sóhun táwọn èèyàn náà ń sọ tàbí pé ká wo àwòrán tí wọ́n ń wò. Dípò tá a fi máa ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká ti ilẹ̀kùn ọkàn wa pa, ká yí ìjíròrò náà pa dà tàbí ká fibẹ̀ sílẹ̀ láìjáfara. Ó gba ìgboyà tá ò bá fẹ́ káwọn ojúgbà wa mú ká máa ronú tàbí hùwà bíi tiwọn. Ohun kan tó dájú ni pé Jèhófà ń rí gbogbo ìsapá wa, á sì fún wa lókun àti ọgbọ́n tá a nílò láti borí ètekéte Sátánì.—2 Kíró. 16:9; Aísá. 40:29; Ják. 1:5. w19.01 17-18 ¶12-13
Tuesday, September 8
Nígbà tí mo ronú lórí gbogbo iṣẹ́ tí ọwọ́ mi ti ṣe . . . , mo rí i pé asán ni gbogbo rẹ̀ . . . kò sí ohun gidi kan.—Oníw. 2:11.
Sólómọ́nì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó sì lágbára. Ó wá pinnu pé òun fẹ́ dán ìgbádùn wò, kóun lè rí ohun rere tó máa tibẹ̀ wá. (Oníw. 2:1-10) Ó kọ́ àwọn ilé ńláńlá, ó sì ṣe àwọn ọgbà ìtura àti ọgbà eléso tó rẹwà, kódà kò sóhun tó fẹ́ tọ́wọ́ rẹ̀ ò tẹ̀. Síbẹ̀, ṣé ó láyọ̀ lẹ́yìn tó kó gbogbo nǹkan yẹn jọ? Ṣé àwọn nǹkan yẹn sì tẹ́ ẹ lọ́rùn? Sólómọ́nì fúnra rẹ̀ sọ fún wa nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Ó dájú pé ẹ̀kọ́ pàtàkì tó yẹ ká fi sọ́kàn lọ̀rọ̀ Sólómọ́nì jẹ́ fún wa. Jèhófà ò fẹ́ kó o jìyà kó o tó gbọ́n. Ó fẹ́ kó o máa ṣègbọràn sí òun, kí ìfẹ́ òun sì gbawájú láyé rẹ. Ká sòótọ́, ó gba ìgbàgbọ́ kó o tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní kábàámọ̀ àwọn ìpinnu tó o ṣe. Sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé ‘ìfẹ́ tó o fi hàn fún orúkọ rẹ̀.’ (Héb. 6:10) Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára. Wàá rí i pé ohun tó dáa jù lọ ni Baba rẹ ọ̀run fẹ́ fún ẹ.—Sm. 32:8. w18.12 22 ¶14-15
Wednesday, September 9
Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ rẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.—Róòmù 5:8.
Ẹni tẹ̀mí máa ń nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó sì máa ń fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Ó máa ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà, ó sì máa ń ṣègbọràn sí i. (1 Kọ́r. 2:12, 13) Àpẹẹrẹ àtàtà ni Dáfídì. Ó kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà ni ìpín tí ó kàn mí àti ti ife mi.” (Sm. 16:5) Dáfídì mọyì “ìpín” rẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà, ìyẹn àjọṣe tó dáa tó ní pẹ̀lú rẹ̀, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé e. (Sm. 16:1) Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ó sọ pé inú òun dùn gan-an. Ó ṣe kedere pé kò sóhun míì tó ń múnú Dáfídì dùn bí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. (Sm. 16:9, 11) Àwọn tó ń wá bí wọ́n á ṣe gbádùn ayé wọn kí wọ́n sì lówó ò lè ní irú ayọ̀ tí Dáfídì ní. (1 Tím. 6:9, 10) Tó o bá nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, tó o sì fayé rẹ sìn ín, ìgbésí ayé rẹ á nítumọ̀, ọkàn rẹ á sì balẹ̀. Àmọ́, báwo lo ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára? O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń wá àkókò láti túbọ̀ mọ Jèhófà. Ìyẹn gba pé kó o máa ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kó o máa kíyè sí àwọn ohun tó dá, kó o sì máa ronú nípa àwọn ànímọ́ tó ní, títí kan bó ṣe ń fìfẹ́ hàn sí ẹ.—Róòmù 1:20. w18.12 25 ¶7-8
Thursday, September 10
Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo èèyàn.—Héb. 13:4.
Kì í ṣe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó ni Pọ́ọ̀lù ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó, kí wọ́n kà á sí ohun iyebíye. Ṣé ojú tíwọ náà fi ń wo ìgbéyàwó nìyẹn, pàápàá ìgbéyàwó rẹ tó bá jẹ́ pé o ti ṣègbéyàwó? Tó o bá ka ìgbéyàwó sí ohun iyebíye, a jẹ́ pé o rẹ́ni fi jọ torí ojú tí Jésù náà fi wò ó nìyẹn. Nígbà táwọn Farisí béèrè lọ́wọ́ Jésù nípa ìkọ̀sílẹ̀, Jésù tọ́ka wọn sí ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ìgbéyàwó àkọ́kọ́, pé: “Ní tìtorí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.” Jésù wá fi kún un pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Máàkù 10:2-12; Jẹ́n. 2:24) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀ àti pé kò fẹ́ káwọn tọkọtaya máa kọ ara wọn sílẹ̀. Ọlọ́run ò sọ fún Ádámù àti Éfà pé wọ́n lè fòpin sí ìgbéyàwó wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlànà ọkọ kan aya kan ni Jèhófà fi lélẹ̀ nígbà tó so wọ́n pọ̀, ó sì fẹ́ kí “àwọn méjèèjì” wà pa pọ̀ títí lọ gbére. w18.12 10-11 ¶2-4
Friday, September 11
Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà.—Róòmù 12:2.
Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, a kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn òfin tó fún wa. Àmọ́ bá a ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà, a bẹ̀rẹ̀ sí í fòye mọ èrò rẹ̀, ìyẹn àwọn ohun tó fẹ́ àtàwọn ohun tí kò fẹ́ tó fi mọ́ ojú tó fi ń wo nǹkan. Tá a bá sì ń jẹ́ kó hàn nínú ìwà wa àtàwọn ìpinnu tá à ń ṣe, ìyẹn á fi hàn pé à ń jẹ́ kí èrò Jèhófà darí wa. Òótọ́ ni pé inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tá a sì ń mọ èrò rẹ̀. Síbẹ̀, kò rọrùn láti máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó torí pé aláìpé ni wá. Bí àpẹẹrẹ, a mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ìṣekúṣe, kíkó ohun ìní jọ, iṣẹ́ ìwàásù, gbígba ẹ̀jẹ̀ sára àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Síbẹ̀, a lè má lóye ìdí tí Jèhófà fi ń fi irú ojú yẹn wò wọ́n. Kí wá la lè ṣe ká lè máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó? Ohun tá a lè ṣe ni pé ká yí èrò inú wa pa dà nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká lè mọ ohun tó fẹ́ ká ṣe, ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kọ́, ká sì jẹ́ kí èrò Ọlọ́run máa darí wa. w18.11 23-24 ¶2-4
Saturday, September 12
Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó tí màá fi ké pè ọ́ pé kí o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá àmọ́ tí o kò dá sí i?—Háb. 1:2.
Àsìkò tí nǹkan le gan-an ni Hábákúkù gbáyé. Àwọn èèyànkéèyàn àtàwọn oníjàgídíjàgan ló yí i ká, èyí sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá a. Hábákúkù lè máa ronú pé, ìgbà wo ni gbogbo wàhálà yìí máa dópin? Kí ló dé tí Jèhófà fi ń wo gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, tí kò sì ṣe nǹkan kan sí i? Gbogbo ibi tí Hábákúkù yíjú sí làwọn èèyàn ti ń rẹ́ni jẹ tí wọ́n sì ń ni àwọn míì lára, àmọ́ kò sóhun tó lè ṣe sí i. Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ló mú kí Hábákúkù gbàdúrà pé kí Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ ó lè máa ṣe é bíi pé Jèhófà ò rí tàwọn rò. Lójú rẹ̀, ó lè dà bíi pé Ọlọ́run ò ní tètè gbé ìgbésẹ̀. Ǹjẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hábákúkù yìí ti ṣe ìwọ náà rí? Ṣé Hábákúkù ò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà mọ́ ni àbí ó ronú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run ò ní ṣẹ? Rárá o! Bí Hábákúkù ṣe sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún Jèhófà fi hàn pé kò bọ́hùn, ó sì gbà pé Jèhófà nìkan ló lè yanjú ọ̀rọ̀ náà kì í ṣe èèyàn. Ó ní ẹ̀dùn ọkàn torí kò mọ ìdí tí Jèhófà ò fi tètè gbé ìgbésẹ̀ tàbí kó jẹ́ pé kò mọ ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba ìwà burúkú tó ń ṣẹlẹ̀. w18.11 14 ¶4-5
Sunday, September 13
Ẹ má to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ayé mọ́.—Mát. 6:19.
Apẹja ni Pétérù àti Áńdérù, àmọ́ nígbà tí Jésù sọ pé òun máa sọ wọ́n di “apẹja ènìyàn,” wọ́n ‘pa àwọ̀n’ wọn tì. (Mát. 4:18-20) Èyí ò túmọ̀ sí pé àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀, torí pé èèyàn gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kó lè bójú tó ìdílé rẹ̀. (1 Tím. 5:8) Bó ti wù kó rí, ẹni tó bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé àwọn nǹkan tara kọ́ ló ṣe pàtàkì jù, kó sì fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Maria. Ó fẹ́ràn kó máa gbá bọ́ọ̀lù kan tí wọ́n ń pè ní gọ́ọ̀fù gan-an, ohun tó sì wù ú ni pé kó di olókìkí nídìí eré bọ́ọ̀lù náà. Àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì nífẹ̀ẹ́ ohun tó ń kọ́. Ohun tó kọ́ mú kó ṣe àwọn ìyípadà kan láyé rẹ̀, èyí sì múnú rẹ̀ dùn gan-an. Ó wá rí i pé òun ò lè fi nǹkan tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́, kóun sì tún máa lé àtidi olókìkí nínú ayé. (Mát. 6:24) Torí náà, ó yááfì eré bọ́ọ̀lù tó fẹ́ràn náà, kò sì lépa àtidi olówó àti olókìkí mọ́. Ní báyìí, ó ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó sì ń gbádùn rẹ̀ gan-an, kódà ó sọ pé: “Iṣẹ́ yìí ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀, kò síṣẹ́ míì tó lè fún mi láyọ̀ tó yìí.” w18.11 5 ¶9-10
Monday, September 14
Káfíńtà yẹn nìyí, ọmọ Màríà. —Máàkù 6:3.
Nígbà tí Jésù pé ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún, ó pa iṣẹ́ káfíńtà náà tì torí ó mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù. Òun fúnra ẹ̀ sọ pé ọ̀kan lára ìdí tí Jèhófà fi rán òun wá sáyé ni láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 20:28; Lúùkù 3:23; 4:43) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ni Jésù fi sípò àkọ́kọ́ láyé rẹ̀, ó sì gba àwọn míì níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 9:35-38) Lónìí, a lè má kọ́ṣẹ́ káfíńtà, àmọ́ ó dájú pé gbogbo wa la jẹ́ òjíṣẹ́ tó ń wàásù ìhìn rere. Iṣẹ́ yìí ṣe pàtàkì gan-an torí pé iṣẹ́ Jèhófà ni, kódà Bíbélì pè wá ní “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 3:9; 2 Kọ́r. 6:4) A sì mọ̀ pé “òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run].” (Sm. 119:159, 160) Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń sapá láti “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́” nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí. (2 Tím. 2:15) Bíbélì ni ìwé tó gbawájú nínú àwọn nǹkan tá à ń lò láti kọ́ni nípa Jèhófà, Jésù àti Ìjọba náà. Torí náà, ó yẹ ká sapá ká lè túbọ̀ di ọ̀jáfáfá nínú bá a ṣe ń lo Bíbélì. w18.10 11 ¶1-2
Tuesday, September 15
Ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tó jẹ́ aláìlera, [kí ẹ sì] fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa sọ́kàn.—Ìṣe 20:35.
Tí ọkọ kan bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi tó jẹ́ orí rẹ̀, ìyẹn máa jẹ́ kó rọrùn fún aya rẹ̀ láti fún un ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (Éfé. 5:22-25, 33) Aya tó bá ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ máa gba ti ọkọ rẹ̀ rò, pàápàá tí ọkọ rẹ̀ bá ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó ń bójú tó nínu ìjọ. Táwọn òbí bá ń gba ti ara wọn rò, àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn máa jẹ́ fáwọn ọmọ wọn. Ojúṣe àwọn òbí ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè máa gba tàwọn míì rò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí lè kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n má ṣe máa sáré kiri nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Tí wọ́n bá sì wà níbi àpèjẹ, kí wọ́n jẹ́ kí àwọn àgbàlagbà kọ́kọ́ gba oúnjẹ tiwọn. Síbẹ̀, gbogbo wa nínú ìjọ lè ran àwọn òbí lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ kan bá ṣe ohun tó wú wa lórí, bóyá tó bá wa ṣí ilẹ̀kùn, ó yẹ ká gbóríyìn fún un. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú ọmọ náà máa dùn, á sì jẹ́ kó túbọ̀ wù ú láti máa ṣe nǹkan fáwọn míì. Nípa bẹ́ẹ̀, òun náà á kẹ́kọ̀ọ́ pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” w18.09 29 ¶5-6
Wednesday, September 16
Aṣáájú kan lẹ ní, Kristi. —Mát. 23:10.
Jésù Kristi ti ń jọba lọ́run, àwọn ìtọ́ni tó sì ń fún wa báyìí máa ṣe wá láǹfààní lónìí àti lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, máa ronú nípa àwọn ìbùkún tó o rí nígbà tó o tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó dé lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Nígbà ìjọsìn ìdílé yín, á dáa kẹ́ ẹ jíròrò bí àwọn ìyípadà tó bá ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù ṣe ṣe yín láǹfààní. Tá a bá ń kíyè sí bí àwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run ń fún wa ṣe ń ṣe wá láǹfààní, á túbọ̀ máa yá wa lára láti tẹ̀ lé ìtọ́ni èyíkéyìí tá a bá gbà. Bí àpẹẹrẹ, bá a ṣe ń dín iye ìwé tá à ń tẹ̀ kù ti dín ìnáwó wa kù. Àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tá à ń lò sì ti mú kí ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan túbọ̀ máa lo àwọn ìtẹ̀jáde tó wà lórí fóònù àtàwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé míì tó bá ṣeé ṣe. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Jésù nìyẹn, àá sì jẹ́ kí ètò Ọlọ́run máa náwó sórí àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì. Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Kristi ń fún wa, àá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àwọn ará túbọ̀ lágbára, ìyẹn á sì jẹ́ ká wà níṣọ̀kan. w18.10 25-26 ¶17-19
Thursday, September 17
Bí a ṣe ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ sí yín, a ti pinnu pé kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan la máa fún yín, a tún máa fún yín ní ara wa.—1 Tẹs. 2:8.
Tá a bá ń ṣìkẹ́ àwọn ará wa, tá a sì ń bá wọn lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, Jèhófà lè lò wá láti tu ẹnì kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú. (2 Kọ́r. 1:3-6) Àmọ́, máa rántí pé aláìpé làwọn ará wa. Ó yẹ ká máa fi sọ́kàn pé wọn kì í ṣe ẹni pípé torí náà kò sí bí wọn ò ṣe ní máa ṣàṣìṣe. (Oníw. 7:21, 22) Ká rántí pé Jèhófà kì í retí pé káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ. Torí náà, ó yẹ ká máa fara wé Jèhófà, ká sì máa mú sùúrù fáwọn ará wa nígbà tí wọ́n bá ṣàṣìṣe. (Éfé. 4:2, 32) Dípò ká máa hùwà sí wọn bíi pé wọn ò ṣe dáadáa tó tàbí ká máa fi ohun tí wọ́n lè ṣe wé tàwọn míì, ṣe ló yẹ ká máa yìn wọ́n fún ohun tí wọ́n bá ṣe. Tá a bá ń gbóríyìn fún wọn látọkànwá, ọkàn wọn á balẹ̀, ohun tí wọ́n sì ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà á máa fún wọn láyọ̀.—Gál. 6:4. w18.09 16 ¶16-17
Friday, September 18
Oúnjẹ mi ni pé kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi, kí n sì parí iṣẹ́ rẹ̀.—Jòh. 4:34.
Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ dà bí oúnjẹ fún òun. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Bó ṣe jẹ́ pé tá a bá jẹ oúnjẹ aṣaralóore, a máa ní okun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára tá a bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà bá ní ká ṣe, a máa jẹ́ ọlọ́gbọ́n. (Sm. 107:43) Àǹfààní tá a sì máa rí tá a bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n kọjá àfẹnusọ. Bíbélì sọ pé ọgbọ́n “ṣe iyebíye ju iyùn, a kò sì lè mú gbogbo àwọn nǹkan mìíràn tí í ṣe inú dídùn rẹ bá a dọ́gba . . . Ó jẹ́ igi ìyè fún àwọn tí ó dì í mú, àwọn tí ó sì dì í mú ṣinṣin ni a ó pè ní aláyọ̀.” (Òwe 3:13-18) Jésù náà sọ pé: “Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.” (Jòh. 13:17) Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù á máa láyọ̀ kìkì tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Jésù fún wọn. Àwọn ìtọ́ni yìí kì í ṣe ohun tí wọ́n kàn máa tẹ̀ lé lẹ́ẹ̀kan tí wọ́n á sì dáwọ́ dúró, wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé e jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. w18.09 4 ¶4-5
Saturday, September 19
Ọlọ́run sì dá èèyàn ní àwòrán rẹ̀.—Jẹ́n. 1:27.
Ká sọ pé Ádámù àti Éfà ronú nípa ìtọ́ni tí Jèhófà fún wọn ni, wọ́n á rí i pé Jèhófà fẹ́ káwọn máa ro tàwọn míì mọ́ tiwọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjèèjì nìkan ló wà nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà bù kún wọn, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n máa bímọ, kí wọ́n kún ilẹ̀ ayé, kí wọ́n sì ṣèkáwọ́ rẹ̀. (Jẹ́n. 1:28) Bí ire àwọn tí Jèhófà dá ṣe jẹ ẹ́ lọ́kàn, ó yẹ kí ire àwọn ọmọ tí Ádámù àti Éfà máa bí lọ́jọ́ iwájú náà jẹ wọ́n lọ́kàn. Jèhófà fẹ́ kí wọ́n sọ gbogbo ayé di Párádísè fún àǹfààní àwọn ọmọ wọn. Iṣẹ́ ńlá nìyẹn, á sì gba pé kí Ádámù àti Éfà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ wọn fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kíyẹn lè ṣeé ṣe. Àwọn ẹni pípé máa ní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jèhófà kí wọ́n tó lè sọ ayé di Párádísè kí wọ́n sì mú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run. (Héb. 4:11) Ẹ fojú inú wo bí ayọ̀ wọn á ṣe pọ̀ tó lẹ́nu iṣẹ́ náà, ó dájú pé wọ́n á gbádùn ẹ̀ dọ́ba! Ká sòótọ́, Jèhófà ò bá ti bù kún wọn gan-an ká sọ pé wọ́n lo ara wọn fún àǹfààní àwọn míì, ìyẹn á sì jẹ́ kí wọ́n láyọ̀. w18.08 18 ¶2; 19-20 ¶8-9
Sunday, September 20
Ó sọ̀rọ̀ èmi ìránṣẹ́ rẹ láìdáa fún ọba.—2 Sám. 19:27.
Kí lo máa ṣe tó o bá gbọ́ táwọn èèyàn sọ̀rọ̀ rẹ láìdáa? Rántí pé wọ́n sọ̀rọ̀ Jésù àti Jòhánù Oníbatisí náà láìdáa. (Mát. 11:18, 19) Kí wá ni Jésù ṣe? Dípò kó máa wá bó ṣe máa gbèjà ara rẹ̀, ńṣe ló rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n fara balẹ̀ kíyè sí ìwà òun àti ẹ̀kọ́ tóun fi ń kọ́ni. Jésù sọ pé, “a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mát. 11:19) A lè kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì nínú ohun tí Jésù sọ. Ìdí ni pé àwọn èèyàn lè sọ̀rọ̀ wa láìdáa tàbí kí wọ́n ṣàríwísí wa nígbà míì. Ó lè máa ṣe wá bíi pé ká gbèjà ara wa káwọn èèyàn lè mọ̀ pé irọ́ ni wọ́n pa mọ́ wa. Àmọ́, nǹkan kan wà tá a lè ṣe. A lè gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó máa jẹ́ kó hàn kedere sáwọn èèyàn pé irọ́ lẹni náà pa mọ́ wa. Láìsí àní-àní, àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká rí i pé tá a bá ń hùwà tó yẹ Kristẹni, kò sẹ́ni tó máa gba irọ́ èyíkéyìí táwọn èèyàn bá pa mọ́ wa gbọ́. w18.08 6 ¶11-13
Monday, September 21
Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o máa bẹ̀rù, òun ni kí o máa sìn, òun ni kí o rọ̀ mọ́.—Diu. 10:20.
Ohun kan jọra nínú ìtàn Kéènì, Sólómọ́nì àti tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òkè Sínáì. Gbogbo wọn ló láǹfààní láti ‘ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yí padà.’ (Ìṣe 3:19) Èyí fi hàn pé Jèhófà máa ń mú sùúrù fáwọn tó bá ṣàṣìṣe. Àpẹẹrẹ Áárónì jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà. Bákan náà lónìí, Jèhófà máa ń lo àwọn ìtàn inú Bíbélì, àwọn ìtẹ̀jáde tàbí ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ Kristẹni kan láti kìlọ̀ fún wa ká má bàa ṣàṣìṣe. Tá a bá fi àwọn ìkìlọ̀ yìí sọ́kàn, ó dájú pé Jèhófà máa fàánú hàn sí wa. Ó nídìí tí Jèhófà fi ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa. (2 Kọ́r. 6:1) Inú rere yìí máa ń jẹ́ ká lè “kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé.” (Títù 2:11-14) Ohun kan ni pé tá a bá ṣì ń gbé “nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí,” àá máa kojú àwọn àdánwò tó lè mú ká fi Jèhófà sílẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé bíná ń jó, bíjì ń jà, ọ̀dọ̀ Jèhófà la máa wà. w18.07 21 ¶20-21
Tuesday, September 22
Jèhófà mọ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀. —2 Tím. 2:19.
Kí la lè ṣe táá mú kó máa wù wá láti wá ojúure Jèhófà dípò ti ayé? Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ fi àwọn kókó pàtàkì méjì yìí sọ́kàn. Àkọ́kọ́, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń fojúure hàn sáwọn tó bá ń sìn ín tọkàntọkàn. (Héb. 6:10; 11:6) Ó mọyì ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Lójú rẹ̀, ìwà ‘àìṣòdodo’ ló máa jẹ́ tó bá pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tì. Ó “mọ ọ̀nà àwọn olódodo,” ó sì mọ bó ṣe máa dá wọn nídè nígbà àdánwò. (Sm. 1:6; 2 Pét. 2:9) Kókó kejì ni pé: Jèhófà lè fojúure hàn sí wa láwọn ọ̀nà tá ò lérò. Tẹ́nì kan bá ń ṣe ohun tó dáa torí káwọn èèyàn lè yẹ́ ẹ sí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò lè rí èrè kankan gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ti gba èrè rẹ̀ ní kíkún báwọn èèyàn ṣe ń kan sáárá sí i. (Mát. 6:1-5) Jésù wá fi kún un pé Jèhófà “tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀” ń kíyè sí àwọn tó ń ṣe ohun tó dáa tí wọn ò sì wá káwọn èèyàn yẹ́ wọn sí, á sì san olúkúlùkù wọn lẹ́san. w18.07 9 ¶8, 10
Wednesday, September 23
Yéé pe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.—Ìṣe 10:15.
Bí Pétérù ṣe ń ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìran tó rí túmọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ làwọn tí Kọ̀nílíù rán wá sọ́dọ̀ rẹ̀ dé. Ẹ̀mí mímọ́ wá fún un ní ìtọ́ni pé kó tẹ̀ lé wọn lọ sílé Kọ̀nílíù, òun náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ká sọ pé Pétérù ò yí èrò tó ní tẹ́lẹ̀ pa dà, ó dájú pé kò ní wọ ilé Kọ̀nílíù. Ìdí sì ni pé àwọn Júù kì í wọ ilé àwọn tí kì í ṣe Júù. Àmọ́ kí ló mú kí Pétérù fa ẹ̀tanú yìí tu lọ́kàn rẹ̀? Ìran tó rí àti ìtọ́ni tí ẹ̀mí mímọ́ fún un ló mú kó yí èrò rẹ̀ pa dà. Lẹ́yìn tí Pétérù sì gbọ́ àlàyé tí Kọ̀nílíù ṣe, ó sọ lábẹ́ ìmísí pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Ó dájú pé òye tuntun yìí máa jọ Pétérù lójú gan-an! w18.08 9 ¶3-4
Thursday, September 24
Ẹ kórìíra ohun búburú. —Émọ́sì 5:15.
A máa ń sapá gan-an láti yẹra fún àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kórìíra. Àmọ́ àwọn ipò míì máa ń yọjú tó jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ohun tó yẹ ká ṣe ní pàtó. Ní irú àwọn àsìkò bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe ká lè múnú Ọlọ́run dùn? Ẹ̀rí ọkàn tá a fi Bíbélì kọ́ ló máa ràn wá lọ́wọ́. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ìdí nìyẹn tó fi fún wa láwọn ìlànà tá a lè fi kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa. Jèhófà sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” (Aísá. 48:17, 18) Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìlànà Bíbélì, à ń fi Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa nìyẹn. Èyí á sì jẹ́ ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́. Ìlànà ni òótọ́ ọ̀rọ̀ tó máa ń mú ká ronú lọ́nà tó tọ́, ká lè ṣèpinnu tó dáa. Àwọn ìlànà tí Jèhófà fún wa máa ń jẹ́ ká mọ bó ṣe ń ronú àti ìdí tó fi fún wa láwọn òfin kan. w18.06 17 ¶5; 18 ¶8-10
Friday, September 25
Ṣé ó bófin mu láti san owó orí fún Késárì àbí kò bófin mu? —Mát. 22:17.
Nígbà tí “àwọn ọmọlẹ́yìn àjọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù” bi Jésù ní ìbéèrè yìí, wọ́n ronú pé tí Jésù bá sọ pé kò yẹ kí wọ́n máa san owó orí, wọ́n á fẹ̀sùn kàn án pé ó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba. Tí Jésù bá sì sọ pé ó yẹ kí wọ́n máa san án, inú lè bí àwọn tó ń tẹ̀ lé Jésù kí wọ́n sì pa dà lẹ́yìn rẹ̀. Jésù rí i dájú pé òun ò dá sí ọ̀rọ̀ náà, kò sọ bóyá ó yẹ kí wọ́n san án àbí kò yẹ. Lóòótọ́, Jésù mọ̀ pé oníjẹkújẹ làwọn agbowó orí, síbẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ló ṣe pàtàkì jù sí i, ohun tó sì gbájú mọ́ nìyẹn. Jésù mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú gbogbo ìṣòro aráyé. Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún gbogbo àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Torí náà, kò yẹ ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú èyíkéyìí kódà tó bá jọ pé ohun tó tọ́ làwọn èèyàn ń jà fún. Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ làwa Kristẹni gbájú mọ́, a kì í sọ̀rọ̀ burúkú nípa ìjọba tàbí ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn ká wa lára ju bó ṣe yẹ lọ. (Mát. 6:33) Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti fìgbà kan rí jẹ́ abẹnugan lágbo òṣèlú àmọ́ ní báyìí wọ́n ti jáwọ́. w18.06 6 ¶9-11
Saturday, September 26
Àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ wá bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pé àwọn ọmọbìnrin èèyàn rẹwà.—Jẹ́n. 6:2.
Kò dájú pé ìṣekúṣe nìkan ni Sátánì fi tan àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yẹn, ó tún lè sọ fún wọn pé òun á fún wọn lágbára láti máa darí àwọn èèyàn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Sátánì ò fẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ nípa ‘irú-ọmọ obìnrin náà’ ṣẹ. (Jẹ́n. 3:15) Bó ti wù kó rí, Jèhófà fòpin sí gbogbo ọ̀tẹ̀ yẹn nígbà tó mú Ìkún Omi wá, bí gbogbo ìsapá Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yẹn ṣe já sófo nìyẹn. Torí náà a ò gbọ́dọ̀ máa ronú pé a ò lè kó sínú páńpẹ́ ìṣekúṣe àti ìgbéraga. Bí àpẹẹrẹ, àwọn áńgẹ́lì tó ṣọ̀tẹ̀ yẹn ti fi ọ̀pọ̀ ọdún sin Jèhófà lọ́run. Síbẹ̀, wọ́n jẹ́ kí èròkerò gbà wọ́n lọ́kàn débi tí wọ́n fi kẹ̀yìn sí Jèhófà. Bákan náà, àwa náà lè ti máa sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, síbẹ̀ tá ò bá ṣọ́ra, èròkerò lè gbà wá lọ́kàn. (1 Kọ́r. 10:12) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká máa yẹ ọkàn wa wò nígbà gbogbo, ká má ṣe fàyè gba èròkerò àti ìgbéraga!—Gál. 5:26; Kól 3:5. w18.05 25 ¶11-12
Sunday, September 27
Mo ní ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀ àti ìrora tí kò dáwọ́ dúró nínú ọkàn mi. —Róòmù 9:2.
Ó dun Pọ́ọ̀lù gan-an nígbà tó rí i pé àwọn Júù kọtí ikún sí ìhìn rere Ìjọba náà. Síbẹ̀ kò torí ìyẹn pa wọ́n tì. Nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù, ó sọ bí ọ̀rọ̀ àwọn Júù ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Ìfẹ́ rere ọkàn-àyà mi àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọ́run fún wọn, ní tòótọ́, jẹ́ fún ìgbàlà wọn. Nítorí mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:1, 2) Pọ́ọ̀lù sọ ìdí tóun ò fi jẹ́ kó sú òun láti máa wàásù fáwọn Júù. Kò jáwọ́ torí “Ìfẹ́ rere ọkàn-àyà” tó ní sí wọn. Ó wù ú pé káwọn Júù rí ojú rere Ọlọ́run, kí wọ́n sì rí ìgbàlà. (Róòmù 11:13, 14) Ṣe ni Pọ́ọ̀lù máa ń bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ káwọn Júù tẹ́wọ́ gba ìhìn rere. Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run.” Pọ́ọ̀lù kíyè sí ibi tí wọ́n dáa sí, ó sì rí i pé wọ́n nítara. Látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀, ó mọ̀ pé tí wọ́n bá lo ìtara wọn lọ́nà tó tọ́, wọ́n á di ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ń fìtara polongo ìhìn rere náà. w18.05 13 ¶4; 15-16 ¶13-14
Monday, September 28
Ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró nìkan ni kí ẹ máa sọ bó bá ṣe yẹ, kí ó lè ṣe àwọn tó ń gbọ́ yín láǹfààní.—Éfé. 4:29.
Ó yẹ kí gbogbo wa máa kíyè sí ohun tó jẹ́ “àìní” àwọn míì. Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù níyànjú pé: “Ẹ mú àwọn ọwọ́ rírọ̀ jọwọrọ àti àwọn eékún tí ó ti di ahẹrẹpẹ nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì máa bá a lọ ní ṣíṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ yín, kí ohun tí ó rọ má bàa yẹ̀ kúrò ní oríkèé, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí a lè mú un lára dá.” (Héb. 12:12, 13) Gbogbo wa pátá títí kan àwọn ọmọdé ló yẹ kó máa fún àwọn míì níṣìírí. Pọ́ọ̀lù fún gbogbo àwọn tó wà níjọ Fílípì nímọ̀ràn pé: “Nígbà náà, bí ìṣírí èyíkéyìí bá wà nínú Kristi, bí ìtùnú onífẹ̀ẹ́ èyíkéyìí bá wà, bí àjọpín ẹ̀mí èyíkéyìí bá wà, bí àwọn ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti àwọn ìyọ́nú èyíkéyìí bá wà, ẹ mú ìdùnnú mi kún ní ti pé ẹ ní èrò inú kan náà, ẹ sì ní ìfẹ́ kan náà, bí a ti so yín pọ̀ nínú ọkàn, kí ẹ ní ìrònú kan ṣoṣo nínú èrò inú yín, láìṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ, kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”—Fílí. 2:1-4. w18.04 22 ¶10; 23 ¶12
Tuesday, September 29
Ẹ wà lómìnira, kí ẹ . . . sì [lo] òmìnira yín . . . bí ẹrú Ọlọ́run. —1 Pét. 2:16.
Tá ò bá fẹ́ ṣi òmìnira wa lò, tá ò sì fẹ́ káyé sọ wá dà bí wọ́n ṣe dà, ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni pé ká jẹ́ kọ́wọ́ wa dí nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Gál. 5:16) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Nóà àti ìdílé rẹ̀. Àárín àwọn èèyàn tó ń hùwà ipá tí wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe ni wọ́n gbé. Síbẹ̀, wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn náà kéèràn ràn wọ́n. Ọgbọ́n wo ni wọ́n dá sí i? Wọ́n jẹ́ kí ọwọ́ wọn dí nínú iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wọn. Bí wọ́n ṣe ń kan ọkọ̀ áàkì náà ni wọ́n ń ṣètò oúnjẹ táwọn àti àwọn ẹranko máa jẹ, wọ́n sì tún ń wàásù ìdájọ́ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Bíbélì sọ pé: ‘Nóà ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.’ (Jẹ́n. 6:22) Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Nóà àti ìdílé rẹ̀ la ìparun ayé búburú yẹn já.—Héb. 11:7. w18.04 10 ¶8; 11 ¶11-12
Wednesday, September 30
Gbogbo àṣẹ yìí àti ògo wọn ni màá fún ọ, torí a ti fi lé mi lọ́wọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sì wù mí ni màá fún. —Lúùkù 4:6.
Kì í ṣe àwọn ìjọba ayé nìkan ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ń lò láti tan àwọn èèyàn jẹ, ó tún máa ń lo ìsìn èké àti ètò ìṣòwò láti ṣi “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé” pátá lọ́nà. (Ìṣí. 12:9) Sátánì máa ń lo ìsìn èké láti tan irọ́ kálẹ̀ nípa Jèhófà. Kì í ṣèyẹn nìkan, Èṣù tún ń sapá gan-an láti mú káwọn èèyàn gbàgbé orúkọ Ọlọ́run. (Jer. 23:26, 27) Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ló ti tàn jẹ torí wọ́n rò pé Ọlọ́run làwọn ń sìn àmọ́ tó jẹ́ pé ẹ̀mí èṣù ni wọ́n ń jọ́sìn. (1 Kọ́r. 10:20; 2 Kọ́r. 11:13-15) Sátánì tún máa ń lo ètò ìṣòwò láti tan àwọn èèyàn jẹ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ rò pé ó dìgbà táwọn bá lówó tabua, táwọn sì kó nǹkan jọ pelemọ káwọn tó lè láyọ̀. (Òwe 18:11) Àwọn tó gba irọ́ yìí gbọ́ máa ń fi ojoojúmọ́ ayé wọn lépa “Ọrọ̀” dípò kí wọ́n máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Mát. 6:24) Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ti jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún owó àtàwọn nǹkan tara bo ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run mọ́lẹ̀.—Mát. 13:22; 1 Jòh. 2:15, 16. w18.05 23 ¶6-7