ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es20 ojú ìwé 98-108
  • October

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • October
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Thursday, October 1
  • Friday, October 2
  • Saturday, October 3
  • Sunday, October 4
  • Monday, October 5
  • Tuesday, October 6
  • Wednesday, October 7
  • Thursday, October 8
  • Friday, October 9
  • Saturday, October 10
  • Sunday, October 11
  • Monday, October 12
  • Tuesday, October 13
  • Wednesday, October 14
  • Thursday, October 15
  • Friday, October 16
  • Saturday, October 17
  • Sunday, October 18
  • Monday, October 19
  • Tuesday, October 20
  • Wednesday, October 21
  • Thursday, October 22
  • Friday, October 23
  • Saturday, October 24
  • Sunday, October 25
  • Monday, October 26
  • Tuesday, October 27
  • Wednesday, October 28
  • Thursday, October 29
  • Friday, October 30
  • Saturday, October 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2020
es20 ojú ìwé 98-108

October

Thursday, October 1

Ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.​—Róòmù 12:15.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà àti Jésù nìkan ló lè rí ohun tó wà lọ́kàn àwọn míì, síbẹ̀ a lè fòye mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn àti ohun tí wọ́n nílò. (2 Kọ́r. 11:29) Òótọ́ ni pé àwọn tí kò mọ̀ ju tara wọn nìkan ló kúnnú ayé yìí, àmọ́ ní tiwa a máa ń sapá láti “wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe [tiwa] nìkan.” (Fílí. 2:4) Ó ṣe pàtàkì gan-an káwọn alàgbà lẹ́mìí ìgbatẹnirò. Ìdí ni pé wọ́n máa jíhìn fún Jèhófà nípa bí wọ́n ṣe bójú tó àwọn àgùntàn tó fi síkàáwọ́ wọn. (Héb. 13:17) Kí àwọn alàgbà tó lè ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn lọ́wọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ máa gba tiwọn rò. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe é? Alàgbà tó ń báni kẹ́dùn tó sì ń gba tàwọn ará rò máa ń lo àkókò pẹ̀lú wọn. Ó máa ń béèrè bí nǹkan ṣe ń lọ, ó sì máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn. Ìyẹn ṣe pàtàkì gan-an tí ẹnì kan nínú ìjọ bá fẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ àmọ́ tí kò mọ bó ṣe fẹ́ sọ ọ́. (Òwe 20:5) Tí alàgbà kan bá ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn ará, àwọn ará á fọkàn tán an, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àjọṣe tó wà láàárín wọn á sì túbọ̀ gún régé.​—Ìṣe 20:37. w19.03 17 ¶14-17

Friday, October 2

Bí àwọn èso ápù oníwúrà tó wà nínú abọ́ fàdákà ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.​—Òwe 25:11.

Téèyàn bá mọyì oore tí wọ́n ṣe é àmọ́ tí kò fi í hàn, ṣe ló dà bí ẹni tó ń dá jẹ oúnjẹ aládùn. Àmọ́ téèyàn bá fi ìmoore hàn, ṣe ló dà bí ẹni tó ní káwọn míì bá òun jẹ nínú oúnjẹ náà, ó ṣe tán wọ́n sọ pé àjọjẹ ló máa ń dùn. Tó bá hàn sí wa pé àwọn èèyàn mọyì wa tàbí ohun tá a ṣe fún wọn, inú wa máa ń dùn. Táwa náà bá ń fi hàn pé a moore, a máa múnú àwọn míì dùn. Ẹni tó ṣe wá lóore tá a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ á mọ̀ pé a mọyì òun, á sì gbà pé ìsapá òun kò já sásán. Nípa bẹ́ẹ̀, okùn ọ̀rẹ́ wa á túbọ̀ lágbára. Ohun iyì ni téèyàn bá ń dúpẹ́ oore, bí ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní ṣe sọ. Báwo lẹ rò pó ṣe máa rí tí wọ́n bá fi èso ápù tó jẹ́ góòlù sínú àwo fàdákà? Ǹjẹ́ kò ní dùn ún wò? Kódà, àrímáleèlọ ni! Jẹ́ ká sọ pé wọ́n firú ẹ̀ ta ẹ́ lọ́rẹ, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ? Bó o ṣe mọyì ápù góòlù yẹn náà làwọn èèyàn ṣe máa mọyì ẹ̀mí ìmoore tó o bá fi hàn. Kókó míì rèé o: Tí wọ́n bá fún ẹnì kan nírú ápù bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ṣe lá tọ́jú ẹ̀ pa mọ́, kò sì ní jẹ́ kó sọnù láé. Lọ́nà kan náà, tá a bá fi ìmoore hàn fún ohun tẹ́nì kan ṣe fún wa, jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ lá máa rántí. w19.02 15 ¶5-6

Saturday, October 3

Ọkùnrin náà ti dà bí ọ̀kan lára wa, ó ti mọ rere àti búburú.​—Jẹ́n. 3:22.

Nígbà tí Ádámù àti Éfà jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, ṣe ni wọ́n jẹ́ kó hàn kedere pé àwọn ò fẹ́ kí Jèhófà máa ṣàkóso àwọn àti pé àwọn á máa fúnra àwọn pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Àmọ́, ẹ wo adúrú nǹkan tí wọ́n pàdánù torí ìpinnu tí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n pàdánù àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà. Wọ́n tún pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti wà láàyè títí láé, àwọn àtọmọdọ́mọ wọn sì tipa bẹ́ẹ̀ jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:12) Ohun tí ìwẹ̀fà ará Etiópíà kan ṣe nígbà tí Fílípì wàásù fún un yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Ádámù àti Éfà ṣe. Ìwẹ̀fà náà mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún un débi pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ṣèrìbọmi. (Ìṣe 8:​34-38) Táwa náà bá ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, tá a sì ṣèrìbọmi bíi ti ìwẹ̀fà yẹn, ṣe là ń jẹ́ kó hàn kedere pé a mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa. A tún ń fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a sì gbà pé òun ló yẹ kó máa pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fún wa. w19.03 2 ¶1-2

Sunday, October 4

Mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀! ​—Jóòbù 27:5.

Ká tó lè sọ pé ẹnì kan jẹ́ oníwà títọ́, ó gbọ́dọ̀ máa hàn nínú ìwà tó ń hù lójoojúmọ́ pé ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ló jẹ ẹ́ lógún jù lọ, pé òun ló ń fayé rẹ̀ sìn àti pé àwọn nǹkan tí Jèhófà kà sí pàtàkì lòun náà kà sí pàtàkì. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “ìwà títọ́” nínú Bíbélì túmọ̀ sí pé kí nǹkan pé, kí ara ẹ̀ dá ṣáṣá, kó má sì ní àbùkù. Bí àpẹẹrẹ, ẹran táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fi rúbọ sí Jèhófà, gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá. (Léf. 22:​21, 22) Òfin náà kò gbà wọ́n láyè láti fi ẹran tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kán, tí etí rẹ̀ re, tí ojú rẹ̀ fọ́ tàbí tó ń ṣàìsàn rúbọ. Ó ṣe pàtàkì kí ẹran tí wọ́n máa fi rúbọ sí Jèhófà dá ṣáṣá, kó má sì lábùkù, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà kò ní tẹ́wọ́ gbà á. (Mál. 1:​6-9) Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ohun tí kò lábùkù ni Jèhófà fẹ́. Ká sọ pé àwa náà bá fẹ́ ra èso, ìwé tàbí ohun èlò míì, ó dájú pé a ò ní gba èyí tó níhò tàbí tí apá kan nínú rẹ̀ ti bà jẹ́. Èyí tó pé tí kò sì lábùkù la máa gbà. Lọ́nà kan náà, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ látọkàn wá, kò sì yẹ ká máa ṣe ẹsẹ̀ kan ilé ẹsẹ̀ kan òde. w19.02 3 ¶3

Monday, October 5

Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ronú lé e lórí.​—Sm. 119:97.

Ká lè dáàbò bo ọkàn wa, a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ohunkóhun tó lè sọ ọkàn wa dìbàjẹ́, àmọ́ a tún gbọ́dọ̀ ṣí ọkàn wa sílẹ̀ káwọn nǹkan rere lè wọnú rẹ̀. Láyé àtijọ́, àwọn aṣọ́bodè máa ń ti ilẹ̀kùn pa kí àwọn ọ̀tá má bàa wọlé, àmọ́ láwọn ìgbà mí ì wọ́n máa ń ṣílẹ̀kùn káwọn èèyàn lè kó oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì wọlé. Àbí kí lẹ rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé wọn kì í ṣí ilẹ̀kùn náà rárá? Ó dájú pé ebi máa pa àwọn ará ìlú. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká máa ṣí ilẹ̀kùn ọkàn wa sílẹ̀ kí èrò Ọlọ́run lè wọlé, kó sì máa darí wa. Èrò Jèhófà ló wà nínú Bíbélì, torí náà tá a bá ń kà á, ṣe là ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa kọ́ wa bó ṣe yẹ ká máa ronú, bó ṣe yẹ kí nǹkan rí lára wa àti bó ṣe yẹ ká máa hùwà. Báwo la ṣe lè túbọ̀ jàǹfààní nínú Bíbélì kíkà? Ó ṣe pàtàkì ká máa gbàdúrà. Ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè rí ‘àwọn ohun àgbàyanu’ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.” (Sm. 119:18) Ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò. Tá a bá ń gbàdúrà, tá à ń ka Bíbélì, tá a sì ń ṣàṣàrò, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á jinlẹ̀ lọ́kàn wa, àá sì máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó.​—Òwe 4:​20-22. w19.01 18 ¶14-15

Tuesday, October 6

Ẹ jẹ́ ká máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run . . .  nígbà gbogbo.​—Héb. 13:15.

Jèhófà mọ̀ pé ipò wa yàtọ̀ síra, ẹ̀bùn wa ò sì rí bákan náà. Síbẹ̀, ó mọyì gbogbo ohun tágbára wa gbé. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi rúbọ sí òun. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan máa ń fi àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rúbọ. Àmọ́, àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lè fi “oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì” rúbọ. Kódà, tí ọmọ Ísírẹ́lì kan ò bá lágbára ẹyẹ méjì, Jèhófà gbà pé kó fi “ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà ìyẹ̀fun kíkúnná” rúbọ. (Léf. 5:​7, 11) Ìyẹ̀fun ò wọ́n púpọ̀, àmọ́ Jèhófà mọyì ẹ̀ gan-an tó bá ṣáà ti jẹ́ “ìyẹ̀fun kíkúnná.” Onínúure ni Jèhófà, ó sì ń gba tiwa náà rò. Kò retí pé nígbà tá a bá ń dáhùn, kí ọ̀rọ̀ wa dùn bíi ti Àpólò tàbí ká mọ̀rọ̀ sọ bíi ti Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 18:24; 26:28) Gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa dáhùn nípàdé. Ẹ rántí opó tó fi ẹyọ owó kéékèèké méjì sínú àpótí ọrẹ. Àmọ́ Jèhófà mọyì rẹ̀ gan-an torí gbogbo ohun tágbára rẹ̀ gbé ló ṣe.​—Lúùkù 21:​1-4. w19.01 8-9 ¶3-5

Wednesday, October 7

Gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.​—Mát. 10:22.

A mọ̀ pé àwọn èèyàn máa kórìíra wa torí pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn máa ṣenúnibíni gan-an sáwọn ọmọlẹ́yìn òun láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. (Mát. 24:9; Jòh. 15:20) Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe pé àwọn ọ̀tá máa kórìíra wa nìkan ni, kódà wọ́n á lo ohun ìjà lóríṣiríṣi láti bá wa jà. Lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń bà wá lórúkọ jẹ́, wọ́n máa ń parọ́ burúkú mọ́ wa, wọ́n sì máa ń fojú pọ́n wa. (Mát. 5:11) Jèhófà kì í dá àwọn ọ̀tá yìí lẹ́kun pé kí wọ́n má bá wa jà. (Éfé. 6:12; Ìṣí. 12:17) Àmọ́ kò yẹ ká bẹ̀rù. Jèhófà ṣèlérí pé “ohun ìjà yòówù” tí wọ́n bá fi bá wa jà “kì yóò ṣe àṣeyọrí.” (Aísá. 54:17) Bí ògiri ilé ṣe máa ń dáàbò boni lọ́wọ́ ìjì òjò, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ “ẹ̀fúùfù òjijì àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀.” (Aísá. 25:​4, 5) Ó dájú pé àwọn ọ̀tá wa kò ní lè pa wá run. (Aísá. 65:17) Gbogbo ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run pátápátá ló máa di “aláìjámọ́ nǹkan kan, wọn yóò sì ṣègbé.”​—Aísá. 41:​11, 12. w19.01 6-7 ¶13-16

Thursday, October 8

Ibi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, òmìnira á wà níbẹ̀.​—2 Kọ́r. 3:17.

Ẹ̀yin ọ̀dọ́, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òmìnira, òun náà ló sì mú kó máa wu ọ̀kọ̀ọ̀kan yín láti ní òmìnira. Bó ti wù kó rí, kò fẹ́ kó o ṣi òmìnira náà lò, kó o má bàa kó sínú ìṣòro. Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan tó ń wo àwòrán oníhòòhò, tí wọ́n ń ṣe ìṣekúṣe, tí wọ́n ń ṣeré géle, tí wọ́n jẹ́ ọ̀mùtí tàbí tí wọ́n ń lo oògùn olóró. Ó lè jọ pé wọ́n ń gbádùn ara wọn lóòótọ́, àmọ́ ìgbádùn náà kì í pẹ́. Ohun tó máa ń tẹ̀yìn àwọn nǹkan yìí yọ kì í dáa rárá. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń kó àìsàn, ohun tí wọ́n ń ṣe máa ń di bárakú, ó sì lè yọrí sí ikú. (Gál. 6:​7, 8) Ó ṣe kedere pé ìtànjẹ lásán ni òmìnira tí wọ́n rò pé àwọn ní. (Títù 3:3) Ní ìfiwéra, àwọn èèyàn mélòó lo mọ̀ tó ṣàìsàn torí pé wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì? Ó ṣe kedere pé tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, àá ní ìlera tó dáa, àá sì ní òmìnira tòótọ́. (Sm. 19:​7-11) Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá ń lo òmìnira rẹ bó ṣe tọ́, tó ò ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run, àwọn òbí rẹ á rí i pé o ṣe é fọkàn tán, inú Jèhófà náà á sì dùn sí ẹ.​—Róòmù 8:21. w18.12 22-23 ¶16-17

Friday, October 9

Ọkùnrin á . . . fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́ ìyàwó rẹ̀, wọ́n á sì di ara kan.​—Jẹ́n. 2:24.

Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ló mú kí nǹkan yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, àtìgbà tọ́mọ aráyé ti ń kú ni ikú ti ń ṣàkóbá fún ìgbéyàwó. Èyí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nígbà tó ń ṣàlàyé fún àwọn Kristẹni pé wọn ò sí lábẹ́ Òfin Mósè. Ó sọ fún wọn pé ikú ló máa ń fòpin sí ìgbéyàwó, tí ẹnì kejì á sì láǹfààní láti fẹ́ ẹlòmíì. (Róòmù 7:​1-3) Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àlàyé kíkún nípa ìgbéyàwó. Ó fàyè gba àwọn tó ní ju ìyàwó kan lọ, ó ṣe tán àwọn èèyàn ti ń fẹ́ ju ìyàwó kan lọ kí Ọlọ́run tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin. Bó ti wù kó rí, ó fún irú àwọn bẹ́ẹ̀ lófin, ó pàṣẹ pé àwọn ọkọ ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ àwọn ìyàwó wọn. Bí àpẹẹrẹ, bí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá fẹ́ ẹrú kan níyàwó, tó sì tún wá fẹ́ obìnrin míì, kò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ ìyàwó àkọ́kọ́ dù ú, ó ṣì gbọ́dọ̀ máa pèsè ohun tó nílò fún un, bí oúnjẹ àti aṣọ. Kódà, Ọlọ́run sọ pé ó gbọ́dọ̀ máa dáàbò bò ó, kó sì máa fìfẹ́ hàn sí i. (Ẹ́kís. 21:​9, 10) Àwa ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, àmọ́ òfin yẹn jẹ́ ká rí i pé ojú pàtàkì ni Jèhófà fi ń wo ìgbéyàwó. Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà máa firú ojú yẹn wo ìgbéyàwó? w18.12 10 ¶3; 11 ¶5-6

Saturday, October 10

Ẹ ò ní gbà gbọ́ tí wọ́n bá tiẹ̀ sọ ọ́ fún yín.​—Háb. 1:5.

Lẹ́yìn tí Hábákúkù sọ gbogbo ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún Jèhófà, ó lè máa ronú nípa ohun tí Jèhófà máa ṣe. Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó sì mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára Hábákúkù, torí náà kò bá a wí fún bó ṣe sọ tinú rẹ̀ jáde. Ọlọ́run mọ̀ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn ń kó ìbànújẹ́ bá a, torí náà ó sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù aláìṣòótọ́ fún Hábákúkù. Kódà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun lẹni àkọ́kọ́ tí Jèhófà sọ fún pé òun máa tó pa àwọn oníwàkiwà yẹn run. Jèhófà sọ fún Hábákúkù pé òun máa tó gbé ìgbésẹ̀. Ó fi dá Hábákúkù lójú pé òun máa lo àwọn ará Kálídíà láti fìyà jẹ àwọn èèyànkéèyàn yẹn, ìyẹn àwọn ará Júdà. Nígbà tí Jèhófà sọ pé “ní àwọn ọjọ́ yín,” ohun tó ń sọ ni pé òun máa mú ìdájọ́ wá sórí àwọn èèyàn yẹn nígbà ayé wòlíì Hábákúkù tàbí nígbà ayé àwọn tí wọ́n jọ gbáyé. Ohun tí Jèhófà sọ yìí fi hàn pé ìyà máa jẹ gbogbo àwọn ará Júdà. w18.11 15 ¶7-8

Sunday, October 11

[Ọlọ́run] fẹ́ ká gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.​—1 Tím. 2:4.

Irú ojú wo lo fi máa ń wo onírúurú àwọn èèyàn tí wọn ò tíì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń wá àwọn Júù lọ sínú sínágọ́gù kó lè wàásù fún wọn, síbẹ̀ kò fi ìwàásù rẹ̀ mọ sọ́dọ̀ àwọn Júù nìkan. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà rìnrìn àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́, wọ́n dé ìlú Lísírà. Ńṣe làwọn ará ìlú yẹn fẹ́ sọ àwọn méjèèjì di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, wọ́n rò pé àwọn méjèèjì ni òòṣà Súúsì àti Hẹ́mísì tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀. Ṣé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wá jẹ́ kíyẹn kó sí wọn lórí débi tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe fọ́ńté? Àbí wọ́n fi àǹfààní yẹn jayé orí wọn, ó kúkú ṣe tán àtakò ni wọ́n kojú láwọn ìlú méjì tí wọ́n ti kúrò? Ṣé wọ́n ronú pé báwọn èèyàn ṣe ń yẹ́ àwọn sí yìí máa jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbọ́ ìhìn rere? Rárá o! Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n gbọn ẹ̀wù wọn ya, wọ́n sì ké jáde pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn tí ó ní àwọn àìlera kan náà tí ẹ̀yin ní.”​—Ìṣe 14:​8-15. w18.09 4-5 ¶8-9

Monday, October 12

Àbí ẹ ò mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run ni? . . . Síbẹ̀, ohun tí àwọn kan lára yín jẹ́ tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ a ti wẹ̀ yín mọ́; . . . a ti pè yín ní olódodo.​—1 Kọ́r. 6:​9, 11.

Ká tó lè sọ òtítọ́ di tiwa, ká sì máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, a gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yí ìwà àti èrò wa pa dà. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa irú ìyípadà bẹ́ẹ̀, ó ní: “Gẹ́gẹ́ bí onígbọràn ọmọ, ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ẹ ti ní tẹ́lẹ̀ rí nínú àìmọ̀kan yín, ṣùgbọ́n . . . kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín.” (1 Pét. 1:​14, 15) Torí pé ìwàkiwà wọ àwọn èèyàn ìlú Kọ́ríńtì ìgbàanì lẹ́wù, àwọn tó bá máa sọ òtítọ́ di tiwọn níbẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nígbèésí ayé wọn. Bíi tìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ lónìí ti ní láti jáwọ́ nínú ìwàkiwà kí wọ́n lè sọ òtítọ́ di tiwọn. Pétérù tún rán àwọn Kristẹni ìgbà yẹn létí pé: “Àkókò tí ó ti kọjá lọ ti tó fún yín láti fi ṣe ìfẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè, nígbà tí ẹ ń tẹ̀ síwájú nínú àwọn ìwà àìníjàánu, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àṣejù nídìí wáìnì, àwọn àríyá aláriwo, ìfagagbága ọtí mímu, àti àwọn ìbọ̀rìṣà tí ó lòdì sí òfin.”​—1 Pét. 4:3. w18.11 6 ¶13

Tuesday, October 13

Gbogbo àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun sì di onígbàgbọ́.​—Ìṣe 13:48.

Báwo la ṣe lè rí àwọn tó ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun”? Bíi ti àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà rí wọn ni pé ká lọ wàásù. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ, ó ní: “Ìlú ńlá tàbí abúlé èyíkéyìí tí ẹ bá wọ̀, ẹ wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn.” (Mát. 10:11) A mọ̀ pé àwọn alábòsí, àwọn agbéraga àtàwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè má gbọ́ tiwa. Torí náà, àwọn olóòótọ́, tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tó sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ là ń wá kiri. A lè fi èyí wé ohun tí Jésù máa ń ṣe nígbà tó ń ṣiṣẹ́ káfíńtà. Ó dájú pé tó bá fẹ́ ṣe ilẹ̀kùn, àga tàbí àwọn nǹkan míì, igi tó dáa, tó sì jẹ́ ojúlówó ló máa wá lọ. Tó bá ti rí igi tó dáa, á kó àwọn irinṣẹ́ rẹ̀, á wá lo ọgbọ́n iṣẹ́ tó ní láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ ṣe. Ohun tó yẹ káwa náà ṣe nìyẹn, ká wá àwọn tó ní ọkàn rere ká lè kọ́ wọn ní òtítọ́.​—Mát. 28:​19, 20. w18.10 12 ¶3-4

Wednesday, October 14

Fílípì lọ sí ìlú Samáríà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Kristi fún wọn. ​—Ìṣe 8:5.

Àpẹẹrẹ àtàtà ni Fílípì ajíhìnrere jẹ́ torí pé ó gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láìka ìyípadà tó ṣẹlẹ̀ sí. Lẹ́yìn táwọn alátakò pa Sítéfánù, inúnibíni tó gbóná janjan bẹ̀rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà yẹn, Fílípì ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Ìṣe 6:​1-6) Inúnibíni yìí mú káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù, síbẹ̀ Fílípì ronú nípa bó ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Torí náà, ó lọ sí Samáríà kó lè wàásù torí pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ibẹ̀ ò tíì gbọ́ ìhìn rere. (Mát. 10:5; Ìṣe 8:1) Fílípì múra tán láti lọ síbikíbi tí ẹ̀mí mímọ́ bá darí rẹ̀ lọ, torí náà Jèhófà lò ó láti wàásù láwọn agbègbè tí ìwàásù ò tíì dé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù kórìíra àwọn ará Samáríà, síbẹ̀ Fílípì ò ṣojúsàájú, èyí sì mú kára tù wọ́n. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi tẹ́tí sí i “pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan.” (Ìṣe 8:​6-8) Fílípì gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, èyí sì mú kí Jèhófà bù kún òun àti ìdílé rẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu.​—Ìṣe 21:​8, 9. w18.10 30 ¶14-16

Thursday, October 15

Ẹ . . . jẹ́ ká gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere.​—Héb. 10:24.

Lọ́jọ́ kan tí Jésù wà ní agbègbè Dekapólì, àwọn èèyàn ‘mú ọkùnrin adití kan tí ó ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ wá bá a.’ (Máàkù 7:​31-35) Dípò kí Jésù wo ọkùnrin náà sàn níṣojú ọ̀pọ̀ èèyàn, ńṣe ló “mú un lọ” sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wò ó sàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ṣeé ṣe kójú máa ti ọkùnrin náà láàárín èrò torí ipò tó wà. Jésù mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi wò ó sàn ní ìkọ̀kọ̀. Òótọ́ ni pé àwa ò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu lónìí. Àmọ́ ohun kan wà táwa náà lè ṣe, ó yẹ ká máa kíyè sí bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn ará wa ká sì gba tiwọn rò. Jésù mọ bí nǹkan ṣe rí lára adití yẹn, ó sì gba tiẹ̀ rò. Ìfẹ́ yìí ló ń mú ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn àgbàlagbà àtàwọn aláàbọ̀ ara lọ́wọ́ kódà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn fún wa. (Jòh. 13:​34, 35) Lára ohun tá a lè ṣe ni pé, ká gbé wọn wá sípàdé tàbí ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè ṣe púpọ̀.​—Mát. 13:23. w18.09 29-30 ¶7-8

Friday, October 16

Kí kálukú wa máa ṣe ohun tó wu ọmọnìkejì rẹ̀ fún ire rẹ̀, láti gbé e ró.​—Róòmù 15:2.

Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà la ṣeyebíye lójú rẹ̀. Jésù náà sì nífẹ̀ẹ́ wa, ìdí nìyẹn tó fi fẹ̀mí rẹ̀ rà wá pa dà. (Gál. 2:20) Àwa náà nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lọkùnrin àti lóbìnrin, a sì máa ń ṣìkẹ́ wọn. Torí náà, tá a bá fẹ́ kára tu àwọn ará, Bíbélì gbà wá níyànjú pé “kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 14:19) Ní báyìí ná, à ń fojú sọ́nà fún Párádísè tí Jèhófà ṣèlérí níbi tí ẹni kẹ́ni ò ti ní rẹ̀wẹ̀sì mọ́. Tó bá dìgbà yẹn, kò ní sí àìsàn mọ́, kò ní sí ogun, inúnibíni, ìṣòro ìdílé, ìjákulẹ̀ títí kan ikú tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà. Nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá fi máa parí, gbogbo èèyàn pátápátá ti máa di pípé. Àwọn tó bá la ìdánwò ìkẹyìn já ni Jèhófà máa gbà ṣọmọ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì ní “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn síra wa, ká sì máa gbé ara wa ró, ká lè jọ kọ́wọ̀ọ́ rìn wọnú ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí. w18.09 14 ¶10; 16 ¶18

Saturday, October 17

Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ronú lé e lórí.​—Sm. 119:97.

Kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ kọjá kéèyàn kàn máa kàwé lóréfèé tàbí kó kàn máa fa ìlà sídìí àwọn ìdáhùn. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ ká ronú lórí ohun tí ibẹ̀ kọ́ wa nípa Jèhófà àti ojú tó fi ń wo nǹkan. Ó tún yẹ ká ronú jinlẹ̀ ká lè lóye ìdí tí Ọlọ́run fi sọ pé ká ṣe àwọn nǹkan kan àti ìdí tó fi sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan míì. Kò tán síbẹ̀ o, ó yẹ ká ronú lórí ibi tó ti yẹ ká ṣàtúnṣe nínú èrò wa àti nínú ìṣe wa. Òótọ́ ni pé, ó lè má rọrùn láti ronú lórí gbogbo nǹkan yìí ní gbogbo ìgbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ àá jàǹfààní gan-an tá a bá ń lo ìdajì nínú àkókò tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ láti ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà. (1 Tím. 4:15) Bá a ṣe túbọ̀ ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa “ṣàwárí fúnra” wa pé àwọn ìlànà Jèhófà ló dáa jù. Àá bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ohun tó jẹ́ èrò Jèhófà lórí àwọn nǹkan, àwa náà á sì gbà pé èrò Jèhófà ló bọ́gbọ́n mu jù lọ. Ìyẹn máa jẹ́ ká ‘yí èrò inú wa pa dà,’ àá sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. (Róòmù 12:2) Díẹ̀díẹ̀, àá máa jẹ́ kí èrò Jèhófà darí wa. w18.11 24 ¶5-6

Sunday, October 18

Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá.​—1 Kọ́r. 3:9.

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù sọ pé òun àtàwọn míì tí wọ́n jọ ń wàásù jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” torí pé wọ́n ń fún irúgbìn èso Ìjọba náà, wọ́n sì ń bomi rin irúgbìn náà. (1 Kọ́r. 3:6) Lónìí, táwa náà bá ń lo okun wa, àkókò wa àti gbogbo ohun tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tí Jèhófà gbé fún wa, àwa náà á di “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ mà nìyẹn jẹ́ o! Tá a bá ń lo àkókò àti okun wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, a máa láyọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó láwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, inú wa máa ń dùn tá a bá rí i pé àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń lóye òtítọ́, ìgbàgbọ́ wọn sì túbọ̀ ń lágbára. Bá a sì ṣe ń rí i tí ẹ̀kọ́ òtítọ́ ń yí ìgbésí ayé wọn pa dà, tí wọ́n sì ń sọ ohun tí wọ́n ń kọ́ fún àwọn míì máa mú ká túbọ̀ láyọ̀. Jésù náà láyọ̀ gan-an nígbà táwọn àádọ́rin [70] tó rán jáde “padà dé pẹ̀lú ìdùnnú” torí àṣeyọrí tí wọ́n ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà.​—Lúùkù 10:​17-21. w18.08 20 ¶11-12

Monday, October 19

Ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn ara rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀.​—Òwe 28:26.

A lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé a ti gbọ́n tán àti pé kò sọ́rọ̀ tá ò lè yanjú. A lè máa ronú pé kò sọ́rọ̀ tá ò lè yanjú kódà tá ò bá mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Tí èdèkòyédè bá wà láàárín àwa àtẹnì kan nínú ìjọ, ó rọrùn láti dórí ìpinnu tí kò tọ́ tá a bá gbọ́ nǹkan kan nípa ẹni náà. Tó bá jẹ́ pé ibi tẹ́ni yẹn kù sí là ń wò ṣáá, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí i. Tá a bá wá gbọ́ nǹkan tí kò dáa nípa ẹni yẹn pẹ́nrẹ́n, a lè tètè gbà pé òótọ́ ni. Kí nìyẹn kọ́ wa? Tá a bá ń di àwọn ará wa sínú, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fojú tí kò dáa wò wọ́n torí àwọn ọ̀rọ̀ tí kì í ṣòótọ́ tá a gbọ́ nípa wọn. (1 Tím. 6:​4, 5) Kò yẹ ká máa jowú àwọn ará wa tàbí ká máa ṣe ìlara wọn, torí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tí kò dáa nípa wọn. Dípò ká máa ro èrò tí kò dáa nípa àwọn ará wa, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn ká sì máa dárí jì wọ́n látọkàn.​—Kól. 3:​12-14. w18.08 6 ¶15; 7 ¶18

Tuesday, October 20

Jèhófà . . . ló ni ọ̀run . . . pẹ̀lú ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀.​—Diu. 10:14.

Jèhófà ló dá gbogbo èèyàn, torí náà gbogbo wa pátá jẹ́ tirẹ̀. (Sm. 100:3; Ìṣí. 4:11) Síbẹ̀, látìgbà táláyé ti dáyé ni Ọlọ́run ti máa ń dìídì ya àwọn kan sọ́tọ̀ bí ohun ìní tó jẹ́ àkànṣe. Sáàmù 135 pe àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì ní “àkànṣe dúkìá rẹ̀.” (Sm. 135:4) Bákan náà, ìwé Hóséà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì máa di èèyàn Jèhófà. (Hós. 2:23) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ nígbà tí Jèhófà yan àwọn tí kì í ṣe Júù láti wà lára àwọn tó máa bá Kristi jọba lọ́run. (Ìṣe 10:45; Róòmù 9:​23-26) Bíbélì pe àwọn tí Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ yàn yìí ní “orílẹ̀-èdè mímọ́” àti “àkànṣe ìní” fún Jèhófà. (1 Pét. 2:​9, 10) Àmọ́, àwọn Kristẹni olóòótọ́ tí wọ́n ń retí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé ńkọ́? Jèhófà pe àwọn náà ní “èèyàn mi,” ó sì tún pè wọ́n ní “àwọn àyànfẹ́ mi.”​—Aísá. 65:22. w18.07 22 ¶1-2

Wednesday, October 21

Ẹ ní èrò yìí nínú yín, irú èyí tí Kristi Jésù náà ní, . . . ó fi gbogbo ohun tó ní sílẹ̀, ó [sì] gbé ìrísí ẹrú wọ̀.​—Fílí. 2:​5, 7.

Ó yẹ káwa Kristẹni tòótọ́ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi torí pé ó fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn jẹ́ ọ̀làwọ́. (Mát. 20:28) Á dáa ká bi ara wa pé, ‘Ṣé mo lè túbọ̀ fara wé Jésù ju bí mo ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ lọ?’ (1 Pét. 2:21) A máa rí ojú rere Jèhófà tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ pípé tóun àti Jésù fi lélẹ̀ fún wa. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ wá lọ́kàn, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti bójú tó àìní wọn. Nígbà tí ọkùnrin kan tó jẹ́ Júù bi Jésù pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?”Jésù fi àpèjúwe kan nípa ọkùnrin ará Samáríà dá a lóhùn. Nínú àpèjúwe náà, Jésù jẹ́ kó ṣe kedere sáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti ran àwọn míì lọ́wọ́ títí kan àwọn tí èdè tàbí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwọn, kódà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn. (Lúùkù 10:​29-37) Àpèjúwe yẹn jẹ́ ká rí i pé tá a bá fẹ́ rí ojú rere Jèhófà, a gbọ́dọ̀ múra tán láti ran àwọn míì lọ́wọ́ bíi ti ọkùnrin ará Samáríà náà. w18.08 19 ¶5-6

Thursday, October 22

Mo kí ọ o, ìwọ ẹni tí a ṣojúure sí gidigidi, Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ. ​—Lúùkù 1:28.

Ṣé Jèhófà fojúure hàn sí Màríà fún bó ṣe tọ́jú Jésù títí tó fi dàgbà? Bẹ́ẹ̀ ni. Lára ohun tí Jèhófà ṣe ni pé ó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Màríà àtohun tó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì. Òótọ́ ni pé Màríà ò lè rìnrìn-àjò pẹ̀lú Jésù ní ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ torí pé ó ṣeé ṣe kí ọkọ rẹ̀ ti kú kéyìí sì mú kó pọndandan fún un láti wà ní Násárétì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jésù ṣe ò ṣojú rẹ̀, síbẹ̀ ó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù kú. (Jòh. 19:26) Nígbà tó yá, Màríà náà wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù kí wọ́n tó gba ẹ̀mí mímọ́ ní Pẹ́ńtíkọ́sì. (Ìṣe 1:​13, 14) Ó ṣeé ṣe kóun náà gba ẹ̀mí mímọ́ lọ́jọ́ yẹn. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé òun náà láǹfààní láti wà pẹ̀lú Jésù lọ́run títí láé àti láéláé. Àbí ẹ ò rí i pé Jèhófà ò gbàgbé iṣẹ́ rere tí Màríà ṣe, ó sì san án lẹ́san! w18.07 9 ¶11; 10 ¶14

Friday, October 23

Ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.​—1 Kọ́r. 10:31.

Nígbà tí Jésù wà láyé, ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láwọn ìlànà kan tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n yẹra fún àwọn èrò àti ìwà tó lè mú kéèyàn kó sí páńpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé ìkórìíra lè mú kẹ́nì kan hùwà ipá, èròkerò sì lè mú kéèyàn ṣèṣekúṣe. (Mát. 5:​21, 22, 27, 28) Tá a bá fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ìlànà Jèhófà máa darí wa ká lè mú ìyìn àti ògo wa fún Ọlọ́run. Láwọn ìgbà míì, àwọn Kristẹni méjì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lè ṣèpinnu tó yàtọ̀ síra lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan. Àpẹẹrẹ kan ni ọ̀rọ̀ ọtí mímu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò dẹ́bi fún mímu ọtí níwọ̀nba, àmọ́ ó kìlọ̀ pé a ò gbọ́dọ̀ mutí lámujù tàbí ká mu àmupara. (Òwe 20:1; 1 Tím. 3:8) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé kò sí àwọn ìlànà míì tó yẹ kí Kristẹni kan ronú lé tó bá fẹ́ mutí kódà tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba ló fẹ́ mu? Rárá o. Ìdí ni pé tí ẹ̀rí ọkàn ẹnì kan bá tiẹ̀ gbà á láyè láti mutí, ó ṣì gbọ́dọ̀ ronú nípa bí ìpinnu rẹ̀ ṣe lè ṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn àwọn míì. w18.06 18 ¶10-11

Saturday, October 24

Ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ìwúkàrà Hẹ́rọ́dù.​—Máàkù 8:15.

Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣọ́ra fún ìwúkàrà tàbí ẹ̀kọ́ táwọn Farisí, àwọn Sadusí, àti àjọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù ń gbé lárugẹ. (Mát. 16:​6, 12) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí máa wọ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lọ́kàn torí kò pẹ́ lẹ́yìn táwọn èèyàn fẹ́ fi jọba ló fún wọn ní ìkìlọ̀ yìí. Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú bó ti wù kó kéré mọ. Torí pé táwọn èèyàn bá da ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ òṣèlú, wàhálà àti ìjà ló sábà máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀. Dída ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ òṣèlú wà lára ohun tó mú káwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí máa wọ́nà láti pa Jésù. Àyà wọn ń já bí wọ́n ṣe rí i pé àwọn èèyàn gba ti Jésù, wọ́n ń ronú pé àwọn èèyàn lè sọ ọ́ di olórí kó sì tipa bẹ́ẹ̀ gbapò mọ́ àwọn lọ́wọ́. Wọ́n sọ pé: “Bí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́ lọ́nà yìí, gbogbo wọn yóò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn ará Róòmù yóò wá, wọn yóò sì gba àyè wa àti orílẹ̀-èdè wa.” (Jòh. 11:48) Kódà, Káyáfà tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ló ṣètò bí wọ́n ṣe máa pa Jésù.​—Jòh. 11:​49-53; 18:14. w18.06 6-7 ¶12-13

Sunday, October 25

Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí àgàbàgebè.​—Róòmù 12:9.

Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ míì tí Sátánì fi ń mú àwọn èèyàn ni kéèyàn máa wá fìn-ín ìdí kókò nípa ẹgbẹ́ òkùnkùn. Lónìí, Sátánì ń lo ìsìn èké láti gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ, àmọ́ ó tún máa ń lo eré ìnàjú láti mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìbẹ́mìílò. Àwọn fíìmù, géèmù, ìwé ìròyìn àtàwọn eré orí ìtàgé máa ń jẹ́ kó dà bíi pé kò sóhun tó burú nínú ìbẹ́mìílò. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kó sínú páńpẹ́ yìí? A ò lè retí pé kí ètò Ọlọ́run to orúkọ àwọn eré ìnàjú tó yẹ ká máa wò àtàwọn tí kò yẹ ká máa wò. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kó lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó bá ìlànà Ọlọ́run mu. (Héb. 5:14) Torí náà, tá a bá ń fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà lókè yìí sílò, àá máa ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé kì í ṣe àwọn eré ìnàjú tí mò ń sọ pé káwọn míì má wò lèmi fúnra mi ń wò? Tí àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí àwọn míì bá rí àwọn eré ìnàjú tí mò ń wò, kí ni wọ́n máa rò nípa mi?’ Ká má gbàgbé pé, tí ìwà wa bá bá ohun tá à ń kọ́ àwọn èèyàn mu, a ò ní kó sínú páńpẹ́ Sátánì.​—1 Jòh. 3:18. w18.05 25 ¶13

Monday, October 26

Ohun rere tó wà lọ́kàn mi àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọ́run nítorí wọn ni pé kí wọ́n rí ìgbàlà.​—Róòmù 10:1.

Báwo la ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù? Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ kó máa wù wá láti wá àwọn tó ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” Ìkejì, ó yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó ṣí ọkàn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. (Ìṣe 13:48; 16:14) Silvana tó ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n [30] ọdún sọ pé: “Kí n tó wọ ilé kan láti wàásù, mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n ní èrò tó dáa nípa àwọn tí mo fẹ́ wàásù fún.” Ó tún yẹ ká máa gbàdúrà pé káwọn áńgẹ́lì darí wa lọ sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. (Mát. 10:​11-13; Ìṣí. 14:6) Robert tó ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tó lé lọ́gbọ̀n [30] ọdún sọ pé: “Inú mi dùn pé mò ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tá à ń wàásù fún.” Ìkẹta, a máa ń kíyè sí ibi táwọn èèyàn dáa sí. Carl tó jẹ́ alàgbà, sọ pé: “Mo máa ń gbìyànjú láti mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni tí mo fẹ́ wàásù fún, mo lè kíyè sí bó ṣe rẹ́rìn-ín músẹ́, bó ṣe fèsì tàbí ìbéèrè kan tó béèrè.” Bíi ti Pọ́ọ̀lù, a lè so èso pẹ̀lú ìfaradà. w18.05 15 ¶13; 16 ¶15

Tuesday, October 27

Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì . . . , kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.​—Héb. 10:​24, 25.

Tá a bá gbọ́ nípa bí àwọn tá a ràn lọ́wọ́ ṣe ń tẹ̀ síwájú, ó máa ń múnú wa dùn gan-an. Bó ṣe rí fún àpọ́sítélì Jòhánù náà nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòh. 4) Táwọn aṣáájú-ọ̀nà bá gbọ́ pé ẹni tí wọ́n kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń ṣe dáadáa nínú ètò Ọlọ́run, bóyá ẹni náà tiẹ̀ ti di aṣáájú-ọ̀nà, inú wọn máa ń dùn gan-an, ó sì máa ń fún wọn níṣìírí. Torí náà, tí aṣáájú-ọ̀nà kan bá rẹ̀wẹ̀sì, a lè rán an létí àwọn àṣeyọrí tó ti ṣe sẹ́yìn, ó dájú pé ìyẹn máa tù ú nínú. Ọ̀pọ̀ àwọn alábòójútó àyíká ti sọ bí inú àwọn àti ìyàwó wọn ṣe máa ń dùn tí wọ́n bá gba lẹ́tà ìdúpẹ́ láti ìjọ kan tí wọ́n bẹ̀ wò. Bákan náà, inú àwọn alàgbà, àwọn míṣọ́nnárì, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì máa ń dùn tá a bá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọyì iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. w18.04 23 ¶14-15

Wednesday, October 28

[Ọba] kò sì gbọ́dọ̀ kó ìyàwó rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀, kí ọkàn rẹ̀ má bàa yí pa dà.​—Diu. 17:17.

Sólómọ́nì ṣàìgbọràn, ó sì fẹ́ ọgọ́rùn-ún méje (700) ìyàwó, kódà ó tún ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) wáhàrì. (1 Ọba 11:3) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ nínú àwọn obìnrin yìí ni kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì máa ń bọ̀rìṣà. Èyí fi hàn pé Sólómọ́nì tún rú òfin tí Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì. (Diu. 7:​3, 4) Díẹ̀díẹ̀ ni Sólómọ́nì ń fọwọ́ rọ́ àwọn òfin Jèhófà sẹ́gbẹ̀ẹ́. Èyí sì mú kó hu àwọn ìwà tó burú jáì. Bí àpẹẹrẹ, Sólómọ́nì kọ́ pẹpẹ kan fún òrìṣà Áṣítórétì, ó sì tún kọ́ òmíì fún òrìṣà Kémóṣì. Ibẹ̀ sì lòun àtàwọn ìyàwó rẹ̀ ti ń bọ̀rìṣà. Ibi tó wá burú sí ni pé orí òkè tó wà níwájú Jerúsálẹ́mù níbi tí tẹ́ńpìlì Jèhófà wà ló kọ́ àwọn pẹpẹ yẹn sí! (1 Ọba 11:​5-8; 2 Ọba 23:13) Ó ṣeé ṣe kí Sólómọ́nì máa tan ara rẹ̀ jẹ pé Jèhófà máa gbójú fo ìwà burúkú tóun hù tóun bá ṣáà ti ń rúbọ sí Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì. Àmọ́, òótọ́ kan tó yẹ ká fi sọ́kàn ni pé Jèhófà kì í gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan dá. w18.07 18-19 ¶7-9

Thursday, October 29

Ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́, èyí tí ẹ ó lè fi paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà.​—Éfé. 6:16.

Onírúurú “ohun ọṣẹ́ oníná” ni Sátánì máa ń lò fún wa. Lára ẹ̀ ni irọ́ tó máa ń pa nípa Jèhófà. Ó máa ń jẹ́ ká rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé kò sẹ́ni tó rí tiwa rò. Ida tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) máa ń ronú pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. Ó sọ pé, “Ó máa ń ṣe mí bíi pé Jèhófà jìnnà sí mi àti pé kò fẹ́ jẹ́ Ọ̀rẹ́ mi.” Kí wá ni Ida ṣe? Ó sọ pé: “Àwọn ìpàdé máa ń fún ìgbàgbọ́ mi lókun. Tẹ́lẹ̀, mi ò kì í dáhùn nípàdé, màá kàn jókòó síbẹ̀ lásán torí mo máa ń ronú pé kò sẹ́ni tó kúkú fẹ́ gbọ́ ohun tí màá sọ. Àmọ́ ní báyìí, mo máa ń múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, mo sì máa ń sapá láti dáhùn lẹ́ẹ̀mejì tàbí ẹ̀ẹ̀mẹta.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ida kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan: Apata táwọn ọmọ ogun Róòmù ń lò ti ní bó ṣe fẹ̀ tó, kò ṣeé sọ di kékeré tàbí ńlá. Àmọ́ apata ńlá ti ìgbàgbọ́ táwa ní lè kéré tàbí kó túbọ̀ tóbi. Bóyá ìgbàgbọ́ wa máa kéré tàbí ó máa tóbi, ọwọ́ wa nìyẹn kù sí. (Mát. 14:31; 2 Tẹs. 1:3) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára sí i! w18.05 29-30 ¶12-14

Friday, October 30

Kí ni kí n ṣe kí n lè rí ìgbàlà? ​—Ìṣe 16:30.

Lẹ́yìn tí ìmìtìtì ilẹ̀ náà wáyé ni ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà tó tẹ́tí sí ìhìn rere. (Ìṣe 16:​25-34) Bó sì ṣe rí lónìí náà nìyẹn, àwọn kan lè má nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere tẹ́lẹ̀, àmọ́ nǹkan lè ṣàdédé yí pa dà fún wọn, kíyẹn sì mú kí wọ́n tẹ́tí sí ìhìn rere. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ lè ṣàdédé bọ́ lọ́wọ́ àwọn kan. Ó sì lè jẹ́ pé àìsàn burúkú kan ló ṣàdédé mú ẹlòmíì tàbí kéèyàn wọn kan ṣàdédé fò ṣánlẹ̀, kó sì kú lọ́sàn kan òru kan. Àwọn tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí máa ń ní ìdààmú ọkàn, èyí sì lè mú káyé sú wọn. Àwọn míì tiẹ̀ lè máa béèrè pé, ‘Kí ni màá ṣe tí Ọlọ́run á fi kó mi yọ?’ Nígbà tá a bá rí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, wọ́n lè tẹ́tí sí ìwàásù wa fúngbà àkọ́kọ́ láyé wọn. Torí náà, tá ò bá dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, a máa wà ní ìmúratán láti sọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀ gan-an.​—Aísá. 61:1. w18.05 19-20 ¶10-12

Saturday, October 31

Ẹ̀mí Jèhófà wà lára mi, torí ó ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere. ​—Lúùkù 4:18.

Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn lónìí ni Sátánì ti fọ́ lójú nípa tẹ̀mí, wọn ò sì mọ̀ pé ìsìn àti òṣèlú ti mú àwọn lẹ́rú àti pé ṣe làwọn ń sìnrú torí àwọn nǹkan tara. (2 Kọ́r. 4:4) Ojúṣe àwa ọmọlẹ́yìn Jésù ni láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà kí wọ́n sì wá jọ́sìn rẹ̀ torí pé Jèhófà ló ń fúnni lómìnira. (Mát. 28:​19, 20) Iṣẹ́ kékeré kọ́ niṣẹ́ yìí torí pé a máa kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ilẹ̀ kan, àwọn èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, àwọn míì tiẹ̀ kórìíra wa. Àmọ́ torí pé Jèhófà ló pàṣẹ pé ká máa wàásù, ó yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè lo òmìnira tí mo ní kí n lè túbọ̀ máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?’ Inú wa dùn pé ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ti rí i pé ayé yìí máa tó pa run, torí náà wọ́n ti pinnu láti jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. (1 Kọ́r. 9:​19, 23) Àwọn kan ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà lágbègbè wọn, àwọn kan sì ti lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Àbí ẹ ò rí bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ torí pé wọ́n ń lo òmìnira wọn láti sìn ín ní kíkún!​—Sm. 110:3. w18.04 11-12 ¶13-14

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́