November
Sunday, November 1
Ẹnikẹ́ni tó bá ń jẹ oúnjẹ yìí máa wà láàyè títí láé.—Jòh. 6:58.
Tá a bá ń sin Jèhófà, a máa láǹfààní láti gbádùn gbogbo ohun tí Ádámù àti Éfà pàdánù, títí kan ìyè àìnípẹ̀kun. Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà torí pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú. Síbẹ̀, Jèhófà gbà wọ́n láyè láti bímọ kí wọ́n sì fúnra wọn pinnu bí wọ́n á ṣe tọ́ àwọn ọmọ wọn. Àmọ́ kò pẹ́ tó fi hàn pé ìwà agọ̀ gbáà ni wọ́n hù bí wọ́n ṣe kẹ̀yìn sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, àkọ́bí wọn pa àbúrò rẹ̀, nígbà tó sì yá, ìwà ipá àti ìmọtara-ẹni-nìkan gbilẹ̀ láyé. (Jẹ́n. 4:8; 6:11-13) Bó ti wù kó rí, Jèhófà ti ṣètò ọ̀nà àbáyọ fún àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó bá jọ́sìn òun. (Jòh. 6:38-40, 57) Bó o ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ onísùúrù àti Ọlọ́run ìfẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tó o ní fún un á túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ. Ìyẹn á sì mú kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà dípò kó o kẹ̀yìn sí i bíi ti Ádámù àti Éfà. w19.03 2 ¶3; 4 ¶9
Monday, November 2
Ẹ máa bára yín kẹ́dùn.—1 Pét. 3:8.
Tó o bá fẹ́ lẹ́mìí ìgbatẹnirò, gbìyànjú láti mọ ohun táwọn tó wà nínú ìdílé rẹ ń kojú àti ìṣòro táwọn ará ìjọ ń bá yí. Yàtọ̀ síyẹn, kó àwọn ọ̀dọ́ mọ́ra, títí kan àwọn tó ń ṣàìsàn, àwọn àgbàlagbà àtàwọn tó ti pàdánù àwọn èèyàn wọn. Máa béèrè bí nǹkan ṣe ń lọ sí, kó o sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tí wọ́n bá sọ. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o lóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fi hàn pé ìfẹ́ tá a ní sí wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. (1 Jòh. 3:18) Ó yẹ ká máa lo ìfòyemọ̀ tá a bá fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe tí wọ́n bá ń kojú ìṣòro máa ń yàtọ̀ síra. Ó máa ń yá àwọn kan lára láti sọ̀rọ̀, àmọ́ àwọn míì kì í fẹ́ sọ ohun tó ń ṣe wọ́n fún ẹlòmíì. Lóòótọ́ a fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́, síbẹ̀ a ò gbọ́dọ̀ tojú bọ ọ̀rọ̀ wọn tàbí ká máa béèrè àwọn ìbéèrè tó lè kó ìtìjú bá wọn. (1 Tẹs. 4:11) Kódà táwọn míì bá tiẹ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún wa, a lè má fara mọ́ èrò wọn. Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé bó ṣe rí lára wọn ni wọ́n ṣe sọ ọ́ yẹn. Torí náà, ó yẹ ká yára láti gbọ́rọ̀, ká sì lọ́ra láti sọ̀rọ̀.—Mát. 7:1; Jém. 1:19. w19.03 19 ¶18-19
Tuesday, November 3
Ẹ̀rù . . . bà mí gan-an.—Neh. 2:2.
Ṣé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́ nígbà míì tó o bá fẹ́ wàásù fún àwọn èèyàn? Rántí Nehemáyà. Ààfin ọba alágbára kan ló ti ń ṣiṣẹ́, àmọ́ inú ẹ̀ ò dùn nígbà tó gbọ́ pé ògiri Jerúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀ wọ́n sì ti dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀. (Neh. 1:1-4) Ẹ wo bí àyà ẹ̀ á ṣe máa lù kìkì nígbà tí ọba bi í pé kí nìdí tí ojú rẹ̀ fi kọ́rẹ́ lọ́wọ́. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Nehemáyà gbàdúrà, ó sì dá ọba lóhùn. Jèhófà gbọ́ àdúrà rẹ̀ torí pé ọba náà ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́. (Neh. 2:1-8) Àpẹẹrẹ míì ni ti Jónà. Nígbà tí Jèhófà ní kó lọ bá àwọn ará ìlú Nínéfè sọ̀rọ̀, àyà ẹ̀ já débi pé ṣe ló sá lọ síbòmíì. (Jónà 1:1-3) Àmọ́, Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí, àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ sì mú káwọn ará ìlú Nínéfè yí pa dà. (Jónà 3:5-10) Àpẹẹrẹ Nehemáyà kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà ká tó dáhùn. Àpẹẹrẹ Jónà ní tiẹ̀ sì jẹ́ ká rí i pé Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láìka ẹ̀rù tó ń bà wá sí. w19.01 11 ¶12
Wednesday, November 4
Kò sí ẹni tó fi ilé tàbí [mọ̀lẹ́bí] sílẹ̀ nítorí mi àti nítorí ìhìn rere, tí kò ní gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100) . . . ní báyìí àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀. —Máàkù 10:29, 30.
Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí wa lè yí pa dà. Kí nìdí? Jésù gbàdúrà nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòh. 17:17) Ọ̀rọ̀ náà, “sọ wọ́n di mímọ́” tún lè túmọ̀ sí “yà wọ́n sọ́tọ̀.” Ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa ń mú ká yàtọ̀ sáwọn tó wà nínú ayé, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ìwà àti ìṣe wa yàtọ̀ sí tiwọn. Táwọn èèyàn bá wá kíyè sí i pé ìwà àti ìṣesí wa ti yàtọ̀, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í bínú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò fẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí wa dà rú, síbẹ̀ wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fún wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ta kò wá torí ìgbàgbọ́ wa. Àmọ́ kì í yà wá lẹ́nu tí irú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ torí Jésù sọ pé: “Ní tòótọ́, àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀.” (Mát. 10:36) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù fi dá wa lójú pé èrè tá a máa gbà máa fi ìlọ́po ìlọ́po ju ohunkóhun tá a yááfì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ. w18.11 6 ¶11
Thursday, November 5
Gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè pátá . . . ń dúpẹ́.—Róòmù 16:4.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọyì àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ó sì hàn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ nípa wọn. Ìgbà gbogbo ló máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run torí wọn. Ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun mọyì wọn nínú lẹ́tà tó kọ sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, nínú ẹsẹ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) àkọ́kọ́ nínú ìwé Róòmù orí kẹrìndínlógún (16), ó dárúkọ àwọn ará mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) láìfi ọ̀kan pe méjì. Pọ́ọ̀lù dìídì sọ̀rọ̀ Pírísíkà àti Ákúílà pé “wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn wewu” nítorí òun, ó sì sọ pé Fébè ti “gbèjà ọ̀pọ̀ èèyàn,” títí kan òun. Ó gbóríyìn fún àwọn ará tó wà níjọ yẹn lọ́kùnrin àti lóbìnrin fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ń ṣe. (Róòmù 16:1-15) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé aláìpé làwọn ará tó wà nínú ìjọ Róòmù, síbẹ̀ nígbà tó ń parí lẹ́tà rẹ̀, ibi tí wọ́n dáa sí ló tẹnu mọ́. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yẹn nígbà tí wọ́n ń ka lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sétí gbogbo ìjọ! Kò sí àní-àní pé àárín àwọn àti Pọ́ọ̀lù á túbọ̀ gún régé. Ìbéèrè tó yẹ ká bi ara wa ni pé: Ṣé èmi náà máa ń fi hàn pé mo mọyì àwọn ará tá a jọ wà nínú ìjọ? w19.02 16 ¶8-9
Friday, November 6
Mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀! —Jóòbù 27:5.
Ṣé a gbọ́dọ̀ jẹ́ pípé ká tó lè jẹ́ oníwà títọ́? Ó ṣe tán aláìpé ni wá, a sì máa ń ṣàṣìṣe lọ́pọ̀ ìgbà. Kò yẹ ká bẹ̀rù torí pé kì í ṣe àṣìṣe wa ni Jèhófà ń wò. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Jáà, tó bá jẹ́ pé àṣìṣe lò ń wò, Jèhófà, ta ló lè dúró?” (Sm. 130:3) Ó mọ̀ pé aláìpé ni wá, a sì máa ń dẹ́ṣẹ̀, síbẹ̀ ó máa ń dárí jì wá fàlàlà. (Sm. 86:5) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà mọ ibi tágbára wa mọ, torí náà kò retí pé ká ṣe ju agbára wa lọ. (Sm. 103:12-14) Ó ṣe pàtàkì ká ní ìfẹ́ ká tó lè jẹ́ oníwà títọ́. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ tọkàntọkàn, kò sì gbọ́dọ̀ ní àbùkù. Tá a bá fi gbogbo ọkàn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kódà lójú àdánwò, a jẹ́ pé ìwà tó tọ́ là ń hù yẹn. (1 Kíró. 28:9; Mát. 22:37) A mọ̀ pé ohun tó tọ́ ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe, ohun tó gbà wá lọ́kàn sì ni bí a ṣe máa múnú Baba wa ọ̀run dùn. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, èrò rẹ̀ ló máa ń darí wa nígbà tí a bá fẹ́ ṣèpinnu, èyí sì ń fi hàn pé a jẹ́ oníwà títọ́. w19.02 3 ¶4-5
Saturday, November 7
Dáàbò bo ọkàn rẹ.—Òwe 4:23.
Tá a bá ń ṣe ohun tó tọ́, tá a sì rí àǹfààní tó wà níbẹ̀, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára. (Ják. 1:2, 3) Inú wa máa dùn torí pé ohun tá à ń ṣe ń mú kí Jèhófà fi wá yangàn pé ọmọ òun ni wá, ìyẹn sì ń mú ká túbọ̀ pinnu pé ìfẹ́ rẹ̀ làá máa ṣe. (Òwe 27:11) Tí Sátánì bá gbé ìṣe rẹ̀ dé, àǹfààní nìyẹn jẹ́ láti fi hàn pé tọkàntọkàn la fi ń sin Jèhófà Baba wa ọ̀run. (Sm. 119:113) Bákan náà, a ti pinnu pé bíná ń jó bí ìjì ń jà, àá máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́, ìfẹ́ rẹ̀ làá sì máa ṣe. (1 Ọba 8:61) Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò lè ṣàṣìṣe? Rárá o, torí pé aláìpé ni wá. Tá a bá ṣàṣìṣe, ẹ jẹ́ ká rántí àpẹẹrẹ Ọba Hesekáyà. Ó ṣàṣìṣe, àmọ́ ó ronú pìwà dà, ó sì sin Jèhófà pẹ̀lú “ọkàn-àyà pípé pérépéré” jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (Aísá. 38:3-6; 2 Kíró. 29:1, 2; 32:25, 26) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká fàyè gba èrò Sátánì rárá àti rárá. Ẹ jẹ́ ká máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká ní “ọkàn-àyà ìgbọràn” ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.—1 Ọba 3:9; Sm. 139:23, 24. w19.01 18-19 ¶17-18
Sunday, November 8
Ẹ jẹ́ ká máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run . . . nígbà gbogbo, ìyẹn èso ètè wa tó ń kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba.—Héb. 13:15.
A máa ń jàǹfààní bá a ṣe ń dáhùn nípàdé. (Aísá. 48:17) Lọ́nà wo? Àkọ́kọ́, tá a bá ní in lọ́kàn láti dáhùn nípàdé, a máa múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa. Tá a bá múra sílẹ̀ dáadáa, àá túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí òye wa bá ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa rọrùn fún wa láti fi ohun tá à ń kọ́ sílò. Ìkejì, bá a bá ṣe ń lóhùn sí ìpàdé bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa gbádùn ìpàdé. Ìkẹta, torí pé ó máa ń gba ìsapá láti dáhùn, a ò ní tètè gbàgbé ohun tá a sọ nípàdé. Bákan náà inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ń lóhùn sípàdé. Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ń tẹ́tí sí wa, ó sì mọyì gbogbo bá a ṣe ń sapá láti dáhùn nípàdé. (Mál. 3:16) Jèhófà máa ń fi hàn pé òun mọyì wa bó ṣe ń bù kún wa torí pé à ń sapá láti ṣe ohun tó fẹ́. (Mál. 3:10) A ti wá rí ìdí tó fi yẹ ká máa dáhùn nípàdé. w19.01 8 ¶3; 9-10 ¶7-9
Monday, November 9
Ẹ kórìíra ohun búburú; ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere.—Róòmù 12:9.
Ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni Jèhófà ń gbà bá wa lò. Dípò kó fún wa láwọn òfin jáǹtìrẹrẹ, ṣe ló ń fi sùúrù kọ́ wa ká lè máa tẹ̀ lé òfin ìfẹ́. Ó fẹ́ ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òun, ká sì kórìíra ohun tó burú. Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù kọ́ wa pé téèyàn bá ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run, kò ní kó sínú ẹ̀ṣẹ̀. (Mát. 5:27, 28) Kódà títí wọnú ayé tuntun ni Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run á máa kọ́ wa ká lè máa ṣe ohun tó tọ́, ká sì kórìíra ohun búburú bíi tiẹ̀. (Héb. 1:9) Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ ká ní ara àti ọpọlọ pípé. Wo bó ṣe máa rí ná, o ò ní máa bá àìpé ẹ̀dá wọ̀yá ìjà mọ́, bẹ́ẹ̀ lo ò sì ní jìyà ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ti fà mọ́. Níkẹyìn, wàá gbádùn “òmìnira ológo” tí Ọlọ́run ṣèlérí fún ẹ. (Róòmù 8:21) Ohun kan ni pé ó níbi tí òmìnira wa mọ, bẹ́ẹ̀ lá sì máa rí títí ayé. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé tá a bá jẹ́ kí ìfẹ́ máa darí wa nìkan la máa gbádùn òmìnira tòótọ́.—1 Jòh. 4:7, 8. w18.12 23 ¶19-20
Tuesday, November 10
Kó kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ fún un . . . kó sì ní kó kúrò ní ilé òun.—Diu. 24:1.
Ọmọ Ísírẹ́lì kan lè kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀ tó bá “rí ohun àìbójúmu kan níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Òfin yẹn ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó pè ní “ohun àìbójúmu.” Ó ní láti jẹ́ ohun tó lè fa ìtìjú tàbí ohun tó burú gan-an, kì í ṣe àwọn ẹ̀sùn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. (Diu. 23:14) Ó bani nínú jẹ́ pé nígbà ayé Jésù, ńṣe làwọn Júù ń kọ ìyàwó wọn sílẹ̀ lórí gbogbo ẹ̀sùn. (Mát. 19:3) Ó dájú pé àwa ò ní fẹ́ ṣe irú ẹ̀ láé. Wòlíì Málákì jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi wo ìkọ̀sílẹ̀. Lásìkò tó gbé láyé, ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń hùwà àìṣòótọ́ sáwọn ‘aya ìgbà èwe wọn,’ tí wọ́n sì ń kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bóyá torí àtifẹ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ò fi bẹ́ẹ̀ dàgbà. Málákì wá sọ ojú tí Ọlọ́run fi wo ìwà yẹn, ó sọ pé Ọlọ́run “kórìíra ìkọ̀sílẹ̀.” (Mál. 2:14-16) Ohun tó sọ yìí bá ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì mu, níbi tí Jèhófà ti sọ pé: ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.’ (Jẹ́n. 2:24) Ojú kan náà ni Jésù fi wo ìgbéyàwó nígbà tóun náà sọ pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mát. 19:6. w18.12 11 ¶7-8
Wednesday, November 11
Ìkórè pọ̀, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ò tó nǹkan.—Mát. 9:37.
Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan ti yọ̀ǹda ara wọn láti lọ sìn níbi tó jìnnà sí àdúgbò wọn. Irú ẹ̀mí tí wòlíì Aísáyà ní làwọn náà ní. Nígbà tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ Aísáyà pé: “Ta ni èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa?” Aísáyà dáhùn pé: “Èmi nìyí! Rán mi!” (Aísá. 6:8) Ṣé ìwọ náà lè yọ̀ǹda ara rẹ láti lọ sìn níbi tí àìní wà? Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mát. 9:38) Ǹjẹ́ o lè lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà níbi tí àìní gbé pọ̀ tàbí kó o ran ẹlòmíì lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan gbà pé ọ̀nà tó dáa jù táwọn lè gbà fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ni pé káwọn ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà níbi tí àìní gbé pọ̀. Ǹjẹ́ àwọn ọ̀nà míì wà tó o lè gbà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Kò sí àní-àní pé wà á láyọ̀ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀. w18.08 27 ¶14-15
Thursday, November 12
Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín, bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn.—Héb. 13:5.
Àwọn ìwé Ìhìn Rere jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan tara. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló yan Jósẹ́fù àti Màríà láti jẹ́ òbí Jésù bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lówó lọ́wọ́. (Léf. 12:8; Lúùkù 2:24) Nígbà tí wọ́n bí Jésù, Màríà “tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran kan, nítorí pé kò sí àyè fún wọn nínú yàrá ibùwọ̀.” (Lúùkù 2:7) Ká sọ pé Jèhófà fẹ́ ni, ó lè ṣe iṣẹ́ ìyanu kí Màríà lè bí Jésù sí ibi tó dáa tó sì tura. Àmọ́ ìyẹn kọ́ ló ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà, ohun tó ṣe pàtàkì sí i ni pé kí Jésù dàgbà nínú ìdílé tí wọ́n ti fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run. Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbí Jésù jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan tara. Àwọn òbí kan máa ń fi dandan lé e pé àfi káwọn ọmọ wọn rí towó ṣe tíyẹn bá tiẹ̀ máa kó bá àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà. Bó ti wù kó rí, ohun tó ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà ni àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀. Ṣé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan tara lo fi ń wò ó? Ṣé ìwà àti ìṣe rẹ fi hàn bẹ́ẹ̀? w18.11 24 ¶7-8
Friday, November 13
Aláyọ̀ ni àwọn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!—Sm. 144:15.
Jèhófà ni Ọlọ́run tó ń fúnni láyọ̀, ó sì fẹ́ ká láyọ̀, ìdí nìyẹn tó fi fún wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa jẹ́ ká láyọ̀. (Diu. 12:7; Oníw. 3:12, 13) Ká sòótọ́, kò rọrùn láti jẹ́ aláyọ̀ nínú ayé yìí. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀? Kò rọrùn láti jẹ́ aláyọ̀ nígbà tá a bá ń kojú àwọn ipò tó le koko. Bí àpẹẹrẹ, inú wa kì í dùn téèyàn ẹni bá kú tàbí tí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, tí tọkọtaya ò bá gbọ́ ara wọn yé tàbí tí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń fà kì í ṣe kékeré. Nígbà míì sì rèé, ẹnì kan lè rẹ̀wẹ̀sì torí pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ìṣòro táwọn míì tún máa ń kojú ni káwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ iléèwé wọn máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn míì sì máa ń kojú inúnibíni tàbí kí wọ́n tiẹ̀ sọ wọ́n sẹ́wọ̀n nítorí òtítọ́. Ìlera àwọn kan túbọ̀ ń burú sí í, ó sì lè jẹ́ àìsàn tó le koko tàbí ìsoríkọ́ ló ń kó ìdààmú bá àwọn míì. Àmọ́, Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pe Jésù Kristi máa ń tu àwọn èèyàn nínú, ó sì fẹ́ kí wọ́n láyọ̀. Kódà Bíbélì pe Jésù ní “aláyọ̀ àti Ọba Alágbára Gíga kan ṣoṣo náà.” (1 Tím. 6:15; Mát. 11:28-30) Nínú ìwàásù Jésù lórí òkè, ó mẹ́nu ba àwọn ànímọ́ tó ṣe pàtàkì tó yẹ ká ní tá a bá fẹ́ láyọ̀ láìka àwọn ìṣòro tá à ń kojú nínú ayé Sátánì sí. w18.09 17-18 ¶1-3
Saturday, November 14
Ẹ ò gbọ́dọ̀ kọ ara yín ní abẹ tàbí kí ẹ fá iwájú orí yín torí òkú. —Diu. 14:1.
Ọ̀kan lára ohun tó máa ń ṣòro jù láti jáwọ́ nínú ẹ̀ làwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. (Òwe 23:23) Ó lè rọrùn fáwọn kan láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó máa ń ṣòro gan-an fáwọn míì. Àwọn tí kì í rọrùn fún lè máa bẹ̀rù pé àwọn á tẹ́ lójú àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Inú àwọn èèyàn kì í dùn rárá sẹ́ni tí kò bá lọ́wọ́ sí àwọn àṣà ìbílẹ̀, pàápàá èyí tí wọ́n fi ń tu òkú lójú. Nírú ipò yìí, àpẹẹrẹ àwọn tó fìgboyà ṣèpinnu lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó pọn dandan. Àyípadà wo làwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nílùú Éfésù àmọ́ tí wọ́n jẹ́ pidánpidán tẹ́lẹ̀ ṣe? Bíbélì sọ pé: “[Wọ́n] kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn. Wọ́n sì ṣe àròpọ̀ iye owó wọn, wọ́n sì rí i pé wọ́n tó ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ẹyọ fàdákà.” (Ìṣe 19:19, 20) Nǹkan ńlá làwọn Kristẹni olóòótọ́ yìí yááfì àmọ́ ìbùkún tí wọ́n rí kọjá àfẹnusọ. w18.11 7 ¶15-16
Sunday, November 15
Nígbà tí wọ́n dádọ̀dọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè náà tán, wọ́n dúró síbi tí wọ́n pàgọ́ sí títí ara wọn fi jinná. —Jóṣ. 5:8.
Kò pẹ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá Jọ́dánì ni Jóṣúà rí ohun kan tó ṣàjèjì. Bó ṣe dé ìtòsí Jẹ́ríkò, ó pàdé ọkùnrin kan tó mú idà lọ́wọ́. Òun ni “olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà,” tó máa dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Jóṣ. 5:13-15) Áńgẹ́lì náà fún Jóṣúà ní ìtọ́ni tó ṣe kedere nípa bó ṣe máa gba ìlú Jẹ́ríkò. Ohun tí áńgẹ́lì náà ní kí Jóṣúà ṣe lè kọ́kọ́ dà bí ohun tí kò mọ́gbọ́n dání. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ní kí Jóṣúà dádọ̀dọ́ fún gbogbo àwọn ọkùnrin. Tó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọkùnrin náà ò ní lókun láti jagun títí tára wọn á fi jinná. (Jẹ́n. 34:24, 25; Jóṣ. 5:2) Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn máa ronú pé, ‘Táwọn ọ̀tá bá kógun wá, báwo la ṣe máa dáàbò bo ìdílé wa?’ Ṣùgbọ́n, ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀! Wọ́n gbọ́ ìròyìn pé ọkàn àwọn ará Jẹ́ríkò ti domi. Bíbélì sọ pé: “Jẹ́ríkò ni a tì pa gbọn-in gbọn-in nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sí ẹnì kankan tí ń jáde, kò sì sí ẹnì kankan tí ń wọlé.” (Jóṣ. 6:1) Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí máa jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀. w18.10 23 ¶5-7
Monday, November 16
Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Èèyàn bíi tiyín ni wá, àwa náà ní àwọn àìlera tí ẹ ní.—Ìṣe 14:15.
Báwo la ṣe lè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Pọ́ọ̀lù? Àkọ́kọ́, kò yẹ ká jẹ́ káwọn èèyàn máa gbé wa gẹ̀gẹ̀ torí àwọn àṣeyọrí tá a ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó ṣe tán kò sí ohun tá a lè dá ṣe láìsí ìtìlẹyìn Jèhófà. Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Irú ojú wo ni mo fi ń wo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù mi? Ṣé kì í ṣe pé mo máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn kan ládùúgbò mi torí pé àwọn èèyàn kì í ka irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sí?’ Inú wa dùn pé kárí ayé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá onírúurú èèyàn tó fẹ́ gbọ́ ìhìn rere níbikíbi tí wọ́n bá wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Nígbà míì, a tiẹ̀ máa ń kọ́ èdè àti àṣà àwọn míì táwọn èèyàn máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú ká lè wàásù fún wọn. A kì í ronú pé a sàn ju irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa ń sún mọ́ wọn ká lè mọ̀ wọ́n dáadáa, ká sì wàásù fún wọn lọ́nà táá wọ̀ wọ́n lọ́kàn. w18.09 5 ¶9, 11
Tuesday, November 17
Júdásì ará Gálílì dìde . . . , ó sì fa àwọn ènìyàn sẹ́yìn ara rẹ̀. —Ìṣe 5:37.
Ọwọ́ ìjọba Róòmù tẹ Júdásì, wọ́n sì pa á. Yàtọ̀ sáwọn Júù alákatakítí yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ń retí Mèsáyà náà torí wọ́n gbà pé òun ló máa gbà wọ́n sílẹ̀ lábẹ́ àjàgà ìjọba Róòmù, á sì sọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè alágbára. (Lúùkù 2:38; 3:15) Wọ́n rò pé Mèsáyà máa gbé ìjọba kan kalẹ̀ ní Ísírẹ́lì, ìyẹn á sì mú káwọn Júù tó ti fọ́n káàkiri pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jòhánù Oníbatisí bi Jésù pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tí Ń Bọ̀, tàbí kí a máa fojú sọ́nà fún ẹnì kan tí ó yàtọ̀?” (Mát. 11:2, 3) Ó ṣeé ṣe kí Jòhánù fẹ́ mọ̀ bóyá Jésù ló máa gba àwọn Júù sílẹ̀ tàbí ẹlòmíì ṣì ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. Bákan náà lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó pàdé méjì nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú ọ̀nà Ẹ́máọ́sì, àwọn ọmọlẹ́yìn náà rò pé Jésù ni Mèsáyà tó máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Róòmù. (Lúùkù 24:21) Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn làwọn àpọ́sítélì Jésù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Olúwa, ìwọ ha ń mú ìjọba padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yìí bí?”—Ìṣe 1:6. w18.06 4 ¶3-4
Wednesday, November 18
Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́.—Òwe 14:15.
Ó yẹ ká ṣọ́ra gan-an tá a bá gbọ́ ìròyìn èyíkéyìí nípa àwa èèyàn Jèhófà. Bíbélì sọ pé gbogbo ìgbà ni Sátánì ń fẹ̀sùn kan àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run. (Ìṣí. 12:10) Jésù tiẹ̀ kìlọ̀ fún wa pé àwọn alátakò máa fi “irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú” nípa wa. (Mát. 5:11) Tá a bá fi ìkìlọ̀ yìí sọ́kàn, inú ò ní bí wa tá a bá gbọ́ táwọn èèyàn ń sọ ohun tí kò dáa nípa àwa èèyàn Jèhófà. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o fi gbogbo ìsọfúnni tó o bá ti rí ránṣẹ́ sáwọn ọ̀rẹ́ rẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ọ̀rọ̀ rẹ dà bíi ti oníròyìn kan tó máa ń fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó máa gbé ìròyìn tuntun kan sáfẹ́fẹ́. Àmọ́, kó o tó fi ìsọfúnni kan ránṣẹ́ lórí fóònù, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ó dá mi lójú pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ìsọfúnni tí mo fẹ́ fi ránṣẹ́ yìí? Ṣé mo tiẹ̀ ti rí àrídájú ẹ̀?’ Tí kò bá dá ẹ lójú àmọ́ tó o fi ránṣẹ́ sáwọn ará, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìròyìn èké lò ń tàn kálẹ̀ láìmọ̀. Torí náà, tí ìsọfúnni kan kò bá dá ẹ lójú, á dáa kó o pa á rẹ́ kúrò lórí fóònù rẹ dípò kó o fi ránṣẹ́ sáwọn míì. w18.08 3 ¶3; 4 ¶6-7
Thursday, November 19
Ẹ sọ ọ́ di àṣà láti máa fúnni, àwọn èèyàn sì máa fún yín.—Lúùkù 6:38.
Jésù mọ̀ pé tá a bá jẹ́ ọ̀làwọ́, a máa láyọ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń mọyì ohun tí ẹlòmíì bá ṣe fún wọn. Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń moore, síbẹ̀ àwọn míì máa ń moore, èyí sì lè mú káwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí í lawọ́ sáwọn míì. Torí náà, táwọn kan ò bá tiẹ̀ moore, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ láti máa fún àwọn èèyàn ní nǹkan látọkàn wá. O ò lè sọ ohun tí oore kan tó o ṣe lónìí máa dà lọ́jọ́ iwájú. Ohun kan ni pé àwọn tó bá lawọ́ kì í fúnni torí ohun tí wọ́n máa rí gbà pa dà. Ohun tí Jésù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Nígbà tí ìwọ bá se àsè, ké sí àwọn òtòṣì, amúkùn-ún, arọ, afọ́jú; ìwọ yóò sì láyọ̀, nítorí tí wọn kò ní nǹkan kan láti fi san án padà fún ọ.” (Lúùkù 14:13, 14) Òǹkọ̀wé Bíbélì kan sọ pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olójú àánú [tàbí ọ̀làwọ́] ni a ó bù kún.” Òmíràn sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀.” (Òwe 22:9; Sm. 41:1) Ó dájú pé, a máa láyọ̀ tá a bá ń fún àwọn míì ní nǹkan. w18.08 21-22 ¶15-16
Friday, November 20
Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Máa kíyè sí i ní gbogbo ọ̀nà rẹ, á sì mú kí àwọn ọ̀nà rẹ tọ́.—Òwe 3:5, 6.
Lónìí, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìsọfúnni tó wà ló kún fún irọ́, àwọn míì sì wà tí kì í ṣe òótọ́ délẹ̀délẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀tọ̀ ni kéèyàn rídìí ọ̀rọ̀ kan, ọ̀tọ̀ sì ni kéèyàn ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Bákan náà, àìpé tiwa fúnra wa náà lè jẹ́ ká dórí èrò tí kò tọ́. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́? Àwọn ìlànà Bíbélì kan wà tá a lè ronú lé. Bí àpẹẹrẹ, ìlànà Bíbélì kan sọ pé ìwà òmùgọ̀ ni téèyàn bá ń fèsì ọ̀rọ̀ kó tó wádìí rẹ̀, èyí sì máa kó ìtìjú bá a. (Òwe 18:13) Ìlànà Bíbélì míì sọ pé ká wádìí ọ̀rọ̀ wò dáadáa ká tó gbà á gbọ́. (Òwe 14:15) Paríparí ẹ̀, láìka iye ọdún tá a ti wà nínú òtítọ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má lọ di pé àá máa gbẹ́kẹ̀ lé òye tara wa. Kò sí àní-àní pé àwọn ìlànà Bíbélì máa ń dáàbò bò wá torí pé ó máa ń jẹ́ ká wádìí ọ̀rọ̀ wò dáadáa, ká ní èrò tó tọ́, ká sì ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. w18.08 7 ¶19
Saturday, November 21
Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba tó ni ìgbésí ayé wa nípa ti ẹ̀mí?—Héb. 12:9.
Nígbà tá a ṣèrìbọmi, ṣe là ń jẹ́ kó ṣe kedere sí gbogbo èèyàn pé a ti di ti Jèhófà àti pé ìfẹ́ rẹ̀ làá máa ṣe. Jésù ṣe ohun kan náà nígbà tó ṣèrìbọmi, ṣe ló dà bí ìgbà tó sọ fún Jèhófà pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run mi, ni inú mi dùn sí.” (Sm. 40:7, 8) Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi? Bíbélì sọ pé: “Lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀, Jésù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú omi; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀, ó sì rí tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀. Wò ó! Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohùn kan wá láti ọ̀run tí ó wí pé: ‘Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.’ ” (Mát. 3:16, 17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ti Jèhófà náà ni Jésù jẹ́ tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ inú Jèhófà dùn nígbà tó rí bí Ọmọ rẹ̀ ṣe múra tán láti ṣe ìfẹ́ òun látọkànwá. Bákan náà, inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ya ara wa sí mímọ́ fún un, ó sì dájú pé á bù kún wa.—Sm. 149:4. w18.07 23 ¶4-5
Sunday, November 22
Ṣé látinú àpáta yìí ni ká ti fún yín lómi ni?— Nọ́ń. 20:10.
Nígbà tí Mósè lo ọ̀rọ̀ náà “kí a,” ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí òun àti Áárónì. Ohun tó sọ yẹn ju ẹnu ẹ̀ lọ torí pé kò fún Jèhófà tó ṣe iṣẹ́ ìyanu náà ní ọ̀wọ̀ tó yẹ ẹ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn torí pé Sáàmù 106:32, 33 sọ pé: “Síwájú sí i, wọ́n fa ìtánni-ní-sùúrù níbi omi Mẹ́ríbà, tí ó fi jẹ́ pé nǹkan burú fún Mósè nítorí wọn. Nítorí pé wọ́n mú ẹ̀mí rẹ̀ korò, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ètè rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà ìwàǹwára.” (Núm. 27:14) Èyí ó wù kó jẹ́, Mósè ò fi ògo fún Jèhófà. Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: ‘Ẹ̀yin méjèèjì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ ìtọ́ni mi.’ (Núm. 20:24) Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá nìyẹn lóòótọ́! Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, Jèhófà ò sì jẹ́ kí odindi ìran náà wọ Ilẹ̀ Ìlérí fún ìwà ọ̀tẹ̀ wọn. (Núm. 14:26-30, 34) Torí náà, ó tọ̀nà, ó sì bá ìdájọ́ òdodo mu pé irú ìdájọ́ kan náà ni Jèhófà ṣe fún Mósè torí ìwà ọ̀tẹ̀ tó hù. Jèhófà ò jẹ́ kí Mósè wọ Ilẹ̀ Ìlérí. w18.07 14 ¶9, 12; 15 ¶13
Monday, November 23
Ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn má jẹ ẹran tàbí kó má mu ọtí tàbí kó má ṣe ohunkóhun tó máa mú arákùnrin rẹ̀ kọsẹ̀.—Róòmù 14:21.
Tá a bá mọ̀ pé arákùnrin kan lè kọsẹ̀ tá a bá mu ọtí, ǹjẹ́ a lè pinnu pé a ò ní mu ọtí lásìkò yẹn ká má bàa mú arákùnrin náà kọsẹ̀? Ó dájú pé àá ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀mùtí paraku làwọn kan kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àmọ́ ní báyìí wọ́n ti pinnu pé àwọn ò ní fẹnu kan ọtí mọ́. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ ṣe ohun táá mú kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pa dà sídìí ìwà tó lè ṣàkóbá fún wọn. (1 Kọ́r. 6:9, 10) Torí náà, kò ní dáa ká máa rọ àwọn míì pé kí wọ́n mutí lẹ́yìn tí wọ́n bá ti sọ pé àwọn ò fẹ́. Nígbà tí Tímótì wà ní nǹkan bí ọmọ ogún ọdún, ó gbà láti dádọ̀dọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrora tí ìyẹn máa fà kì í ṣe kékeré. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó mọ̀ pé àwọn Júù fọwọ́ pàtàkì mú ìdádọ̀dọ́, kò sì fẹ́ mú wọn kọsẹ̀. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, òun náà gba tàwọn míì rò. (Ìṣe 16:3; 1 Kọ́r. 9:19-23) Ṣé ìwọ náà lè ṣe bíi Tímótì kó o yááfì àwọn nǹkan kan torí ẹ̀rí ọkàn àwọn míì? w18.06 18-19 ¶12-13
Tuesday, November 24
Màá yí èdè àwọn èèyàn pa dà sí èdè mímọ́.—Sef. 3:9.
Jèhófà ló máa ń fa àwọn èèyàn wá sínú òtítọ́, á sì mú kí wọ́n di ara ìdílé rẹ̀. (Jòh. 6:44) Tó o bá pàdé ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà fúngbà àkọ́kọ́, nǹkan mélòó ni wàá lè sọ pó o mọ̀ nípa ẹ̀? Ṣàṣà ni nǹkan tí wàá lè sọ nípa onítọ̀hún, yàtọ̀ sí orúkọ rẹ̀ àti bó ṣe rí. Àmọ́ tó bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo pàdé fúngbà àkọ́kọ́, ohun tó o mọ̀ nípa ẹ̀ pọ̀ gan-an. Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ ti wá tàbí pé orílẹ̀-èdè yín, èdè yín tàbí àṣà yín yàtọ̀ síra, ohun tẹ́ ẹ mọ̀ nípa ara yín pọ̀ gan-an! Bí àpẹẹrẹ, gbàrà tẹ́ ẹ bá ti ríra lẹ ti máa mọ̀ pé èdè kan náà lẹ̀ ń sọ, ìyẹn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí Bíbélì pè ní “èdè mímọ́.” Ẹ mọ̀ pé ohun kan náà lẹ gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run, ìlànà kan náà lẹ̀ ń tẹ̀ lé, ìrètí kan náà lẹ ní àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ká sòótọ́, àwọn ohun tó ṣe pàtàkì tó yẹ kéèyàn mọ̀ nípa ẹnì kan nìyí torí pé àwọn nǹkan yẹn ló ń jẹ́ ká fọkàn tán ara wa, kí okùn ọ̀rẹ́ wa sì lágbára. w18.12 21 ¶9-10
Wednesday, November 25
Láìjẹ́ pé ẹ dádọ̀dọ́ . . . , ẹ ò lè rí ìgbàlà.—Ìṣe 15:1.
Lábẹ́ ìdarí Kristi, ìgbìmọ̀ olùdarí mú kó ṣe kedere pé kò pọn dandan káwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù dádọ̀dọ́. (Ìṣe 15:19, 20) Àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni ṣì ń dádọ̀dọ́ fún àwọn ọmọ wọn. Àmọ́ a lè máa ronú pé, ‘Kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ kí ọ̀rọ̀ nípa ìdádọ̀dọ́ pẹ́ tó yìí, ó ṣe tán ikú rẹ̀ ti wọ́gi lé Òfin Mósè?’ (Kól. 2:13, 14) Nígbà tí nǹkan bá yí pa dà tàbí tí ìtọ́ni tuntun bá dé, ó máa ń gba àkókò káwọn kan tó lè ní èrò tó tọ́ nípa àyípadà náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù nìyẹn. (Jòh. 16:12) Ó ṣòro fáwọn kan nínú wọn láti gbà pé èèyàn lè rí ojú rere Ọlọ́run láìjẹ́ pé ó dádọ̀dọ́. (Jẹ́n. 17:9-12) Àwọn míì ń bẹ̀rù pé táwọn ò bá pa Òfin Mósè mọ́, àwọn Júù máa ṣe inúnibíni sáwọn. (Gál. 6:12) Àmọ́ nígbà tó yá, Kristi lo Pọ́ọ̀lù láti kọ lẹ́tà sáwọn ará kó lè fún wọn láwọn ìtọ́ni míì táá jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fáwọn Kristẹni yẹn láti ní èrò tó tọ́.—Róòmù 2:28, 29; Gál. 3:23-25. w18.10 24-25 ¶10-12
Thursday, November 26
Káyáfà ló gba àwọn Júù nímọ̀ràn pé ó máa ṣe wọ́n láǹfààní kí ọkùnrin kan kú torí àwọn èèyàn. —Jòh. 18:14.
Káyáfà rán àwọn sójà pé kí wọ́n lọ mú Jésù ní òru. Ṣùgbọ́n Jésù mọ gbogbo ètekéte wọn. Nígbà tóun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń jẹun lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ó ní kí wọ́n kó idà dání kó lè kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Wọ́n sì kó idà méjì dání. (Lúùkù 22:36-38) Nígbà táwọn tó fẹ́ mú Jésù dé, Pétérù rí i pé òru ni wọ́n fi bojú wá mú un. Èyí múnú bí i débi pé ó fi idà ṣá ọ̀kan lára wọn. (Jòh. 18:10) Àmọ́ Jésù sọ fún Pétérù pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mát. 26:52, 53) Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ àtàtà ni Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan ayé! Ohun tí Jésù sì gbàdúrà fún lálẹ́ ọjọ́ yẹn nìyẹn. (Jòh. 17:16) Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé a ò gbọ́dọ̀ jà kódà tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ, àfi ká fìjà fún Ọlọ́run jà. Síbẹ̀ àwa èèyàn Ọlọ́run ń gbádùn àlàáfíà, a sì wà níṣọ̀kan. Ó dájú pé inú Jèhófà á máa dùn bó ṣe ń rí i táwọn èèyàn rẹ̀ wà níṣọ̀kan láìka ìyapa tó wà nínú ayé.—Sef. 3:17. w18.06 7 ¶13-14, 16
Friday, November 27
Dírágónì náà wá bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn tó ṣẹ́ kù lára ọmọ rẹ̀ jagun.—Ìfi. 12:17.
Yàtọ̀ sí pé Sátánì máa ń lo àwọn ohun tó dà bí ìjẹ kó lè dẹkùn mú wa, ó tún máa ń halẹ̀ mọ́ wa ká lè fi Jèhófà sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú káwọn aláṣẹ dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró. Ó tún lè mú kí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ iléèwé wa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé à ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. (1 Pét. 4:4) Bákan náà, ó lè mú káwọn mọ̀lẹ́bí wa fúngun mọ́ wa ká má bàa lọ sípàdé mọ́. (Mát. 10:36) Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kí la lè ṣe? Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé irú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ torí pé Sátánì ló ń bá wa jagun. (Ìṣí. 2:10) Lẹ́yìn náà, ká máa rántí pé Sátánì ti fẹ̀sùn kàn wá pé ìgbà tí nǹkan bá dẹrùn fún wa nìkan la máa sin Jèhófà. Ó ní tí ìyà bá jẹ wá, a máa fi Jèhófà sílẹ̀. (Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà torí pé òun nìkan ló lè gbà wá lọ́wọ́ Sátánì, ó sì dájú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé!—Héb. 13:5. w18.05 26 ¶14
Saturday, November 28
O ò mọ èyí tó máa ṣe dáadáa.—Oníw. 11:6.
Tó bá tiẹ̀ dà bíi pé àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa, kò yẹ ká fojú kéré ipa tí iṣẹ́ ìwàásù wa lè ní lórí wọn. Òótọ́ kan ni pé, àwọn èèyàn lè má fetí sí wa, àmọ́ wọ́n ń kíyè sí ohun tá à ń ṣe. Wọ́n máa ń rí i pé à ń múra dáadáa, à ń hùwà ọmọlúàbí, a sì máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n lè wá rí i pé èrò tí wọ́n ní nípa wa kì í ṣe òótọ́. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí Sergio àti Olinda tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n sọ pé: “Ìgbà kan wà tá ò lè lọ sí ojúde tá a ti máa ń pín ìwé ìròyìn torí àìlera. Nígbà tá a pa dà síbẹ̀, àwọn tó ń kọjá béèrè pé, ‘Kí ló ṣẹlẹ̀? Ó pẹ́ tá a rí yín o.’ ” Tá ò bá “jẹ́ kí ọwọ́ [wa] sinmi” lẹ́nu iṣẹ́ fífúnrúgbìn ìhìn rere Ìjọba náà, àwa náà ń kópa pàtàkì nínú ṣíṣe “ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” nìyẹn. (Mát. 24:14) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, à ń láyọ̀ bá a ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa. Ìdí sì ni pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn tó ń “so èso pẹ̀lú ìfaradà.”—Lúùkù 8:15. w18.05 16 ¶16-18
Sunday, November 29
Ìyìn ni fún Ọlọ́run . . . tó ń fún wa níṣìírí nínú gbogbo àdánwò wa.—2 Kọ́r. 1:3, 4, àlàyé ìsàlẹ̀.
Ọlọ́run tí ń fúnni níṣìírí ni Jèhófà. Àtìgbà táwa èèyàn ti dẹ́ṣẹ̀ tá a sì ti di aláìpé ló ti ń fún wa níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, kété lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà fún àwọn tó máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù níṣìírí tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ìrètí ṣì wà fún wọn. Lẹ́yìn tá a lóyè àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, ọkàn wa balẹ̀ pé bó pẹ́, bó yá “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” ìyẹn Sátánì Èṣù àti gbogbo iṣẹ́ burúkú rẹ̀ máa pa run. (Ìṣí. 12:9; 1 Jòh. 3:8) Àárín àwọn èèyàn burúkú ni Nóà tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń gbé, kódà òun àti ìdílé rẹ̀ nìkan ló ń sin Jèhófà. Àwọn oníṣekúṣe àti oníwà ipá ló yí wọn ká, ó sì ṣeé ṣe kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Nóà. (Jẹ́n. 6:4, 5, 9, 11; Júúdà 6) Àmọ́, Jèhófà sọ fún Nóà pé òun máa tó pa ayé búburú yẹn run, ó sì jẹ́ kó mọ ohun tó máa ṣe kí òun àti ìdílé rẹ̀ má bàa pa run. (Jẹ́n. 6:13-18) Èyí mú kí Nóà rí i pé Ọlọ́run tí ń fúnni níṣìírí ni Jèhófà. w18.04 15 ¶1-2
Monday, November 30
Ẹ máa fún ara yín níṣìírí, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró, bí ẹ ti ń ṣe ní tòótọ́.—1 Tẹs. 5:11.
Kò yẹ ká máa ronú pé a ò lè fún àwọn míì níṣìírí bóyá torí pé a ò mọ ohun tá a máa sọ. Ká sòótọ́, kò dìgbà tá a bá sọ̀rọ̀ rẹpẹtẹ ká tó lè fúnni ní ìṣírí, kódà a lè má ṣe ju pé ká rẹ́rìn-ín músẹ́ sí ẹnì kan. Tá a bá rẹ́rìn-ín sẹ́nì kan àmọ́ tí kò rẹ́rìn-ín pa dà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nǹkan kan ń jẹ ẹni náà lọ́kàn. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, tá a bá fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, ìyẹn á jẹ́ kí ara tù ú. (Ják. 1:19) Gbogbo wa pátá la lè fún àwọn ará wa tó nílò ìtùnú ní ìṣírí. Ọba Sólómọ́nì sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ tí ó bọ́ sí àkókò mà dára o! Ìtànyòò ojú tàbí ọ̀yàyà a máa mú kí ọkàn-àyà yọ̀; ìròyìn tí ó dára a máa mú àwọn egungun sanra.’ (Òwe 15:23, 30) Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé kíkọ orin Ìjọba Ọlọ́run pa pọ̀ máa ń fúnni ní ìṣírí. (Kól. 3:16; Ìṣe 16:25) Ó ṣe pàtàkì gan-an ká túbọ̀ máa fún ara wa níṣìírí lákòókò yìí torí pé ọjọ́ Jèhófà ti ń “sún mọ́lé.”—Héb. 10:25. w18.04 23 ¶16; 24 ¶18-19