ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es20 ojú ìwé 118-128
  • December

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • December
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Tuesday, December 1
  • Wednesday, December 2
  • Thursday, December 3
  • Friday, December 4
  • Saturday, December 5
  • Sunday, December 6
  • Monday, December 7
  • Tuesday, December 8
  • Wednesday, December 9
  • Thursday, December 10
  • Friday, December 11
  • Saturday, December 12
  • Sunday, December 13
  • Monday, December 14
  • Tuesday, December 15
  • Wednesday, December 16
  • Thursday, December 17
  • Friday, December 18
  • Saturday, December 19
  • Sunday, December 20
  • Monday, December 21
  • Tuesday, December 22
  • Wednesday, December 23
  • Thursday, December 24
  • Friday, December 25
  • Saturday, December 26
  • Sunday, December 27
  • Monday, December 28
  • Tuesday, December 29
  • Wednesday, December 30
  • Thursday, December 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2020
es20 ojú ìwé 118-128

December

Tuesday, December 1

Àánú wọn . . . ṣe é.​—Máàkù 6:34.

Ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ Jésù tó ta yọ jù lọ ni pé ó lóye bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn aláìpé. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó máa ń “yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń yọ̀,” ó sì máa ń “sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn àádọ́rin (70) ọmọlẹ́yìn pa dà dé láti ibi tí wọ́n ti lọ wàásù, inú wọn dùn torí pé iṣẹ́ náà sèso rere, èyí sì mú kí Jésù “yọ̀ gidigidi nínú ẹ̀mí mímọ́.” (Lúùkù 10:​17-21) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, nígbà tí Jésù rí bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣọ̀fọ̀ Lásárù, Bíbélì sọ pé “ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi, ìdààmú sì bá a.” (Jòh. 11:33) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, ó máa ń ṣàánú àwọn èèyàn aláìpé, ó sì máa ń gba tiwọn rò. Kí nìdí? Ìdí pàtàkì kan ni pé Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an. Ó “fẹ́ràn àwọn ọmọ èèyàn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.” (Òwe 8:31) Ìfẹ́ yìí máa ń mú kó lóye báwa èèyàn ṣe ń ronú. Kódà, àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ó mọ ohun tó wà nínú èèyàn.”​—Jòh. 2:25. w19.03 20 ¶1-2

Wednesday, December 2

Na ọwọ́ rẹ, kí o sì kọ lu gbogbo ohun tó ní, ó dájú pé ó máa bú ọ níṣojú rẹ gan-an.​—Jóòbù 1:11.

Sátánì run gbogbo ọrọ̀ àti ohun ìní Jóòbù, ó pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó bà á lórúkọ jẹ́ ládùúgbò, ó sì tún pa ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Kò tán síbẹ̀ o, ó fi àìsàn kọ lù ú, ó jẹ́ kó ní eéwo látorí títí dé àtẹ́lẹsẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́, nígbà tọ́rọ̀ náà dójú ẹ̀ fún ìyàwó Jóòbù, ó ní kí Jóòbù bú Ọlọ́run kó sì kú. Jóòbù fúnra ẹ̀ bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kóun kú. Nígbà tí Sátánì rí i pé Jóòbù ò bọ́hùn, ó dọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ míì, àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta ló sì lò. Ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n lò pẹ̀lú rẹ̀, kàkà kí wọ́n sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un, ọ̀rọ̀ kòbákùngbé ni wọ́n ń sọ sí i, wọ́n sì ń dá a lẹ́bi ṣáá. Wọ́n ní Ọlọ́run ló fa gbogbo àjálù tó dé bá a àti pé ìdúróṣinṣin rẹ̀ kò nítumọ̀ lójú Ọlọ́run. Kódà, wọ́n fẹ̀sùn kan Jóòbù pé èèyàn burúkú ni àti pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ ló ń jẹ!​—Jóòbù 1:​13-22; 2:​7-11; 15:​4, 5; 22:​3-6; 25:​4-6. w19.02 4 ¶7-8

Thursday, December 3

Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n. ​—Sm. 111:10.

Ìbẹ̀rù máa ń ṣe wá láǹfààní nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá bẹ̀rù Jèhófà, a ò ní ṣe ohun tí kò nífẹ̀ẹ́ sí. Ká sọ pé Ádámù àti Éfà bẹ̀rù Ọlọ́run ni, wọn ò ní ṣọ̀tẹ̀ sí i. Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n wá rí i pé àwọn ti ṣẹ̀. Torí náà, kò sí nǹkan míì táwọn ọmọ wọn lè jogún lára wọn ju ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú lọ. Nígbà tó ṣe kedere sí wọn pé àwọn ti ṣẹ̀ sí Jèhófà, ojú tì wọ́n débi pé ṣe ni wọ́n wá nǹkan fi bo ìhòòhò wọn. (Jẹ́n. 3:​7, 21) Ó ṣe pàtàkì pé ká bẹ̀rù Ọlọ́run, àmọ́ kò sídìí kankan tó fi yẹ ká máa bẹ̀rù ikú. Ìdí ni pé Jèhófà ti ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun fún wa. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tá a sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà máa dárí jì wá torí pé a nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé a nígbàgbọ́ ni pé ká ya ara wa sí mímọ́, ká sì ṣèrìbọmi.​—1 Pét. 3:21. w19.03 5-6 ¶12-13

Friday, December 4

Ẹnikẹ́ni ò ṣẹ́ kù lára wọn àfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè àti Jóṣúà ọmọ Núnì.​—Nọ́ń. 26:65.

Ọ̀pọ̀ ìdí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní tó fi yẹ kí wọ́n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Jèhófà ló dá wọn nídè lóko ẹrú Íjíbítì lẹ́yìn tó mú Ìyọnu Mẹ́wàá bá àwọn èèyàn ilẹ̀ náà. Ó mú kí wọ́n la Òkun Pupa já, ó sì mú kí gbogbo ọmọ ogun Íjíbítì kú sínú omi yẹn. Inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dùn débi pé ṣe ni wọ́n ń jó tí wọ́n ń yọ̀, tí wọ́n sì forin yin Jèhófà. Àmọ́ ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ náà rí lára wọn jálẹ̀ ìrìn àjò wọn nínú aginjù? Tí wọ́n bá ti ní ìṣòro, kíá ni wọ́n á gbàgbé gbogbo oore tí Jèhófà ṣe fún wọn, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi hàn pé àwọn ò moore. (Sm. 106:7) Lọ́nà wo? “Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè àti Áárónì.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà ni wọ́n ń kùn sí. (Ẹ́kís. 16:​2, 8) Ohun tí wọ́n ṣe yẹn múnú bí Jèhófà gan-an. Ó wá sọ fún wọn pé gbogbo ìran yẹn ló máa kú sínú aginjù, àyàfi Jóṣúà àti Kálébù.​—Núm. 14:​22-24. w19.02 17 ¶12-13

Saturday, December 5

Oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí.​—Mát. 11:29.

Jésù ò pe àfiyèsí sí ara ẹ̀, kò sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun máa filé pọntí fọ̀nà rokà láti fi rántí ikú òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa fi ètò ráńpẹ́ kan rántí òun lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. (Jòh. 13:15; 1 Kọ́r. 11:​23-25) Ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe agbéraga. Inú wa dùn gan-an pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wà lára àwọn ànímọ́ pàtàkì tí Ọba wa ní. (Fílí. 2:​5-8) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fi ire àwọn mí ì ṣáájú tiwa. (Fílí. 2:​3, 4) Àpẹẹrẹ kan lohun tí Jésù ṣe lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn láyé. Ó mọ̀ pé òun máa tó kú ikú oró, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ ló gbà á lọ́kàn torí ó mọ̀ pé wọ́n máa ṣọ̀fọ̀ òun. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nínú ọ̀rọ̀ tó bá wọn sọ kẹ́yìn, ó fún wọn ní ìtọ́ni àti ìṣírí, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. (Jòh. 14:​25-31) Kò sí àní-àní pé Jésù fi ọ̀rọ̀ àwọn míì ṣáájú tiẹ̀. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa! w19.01 21 ¶5-6

Sunday, December 6

Jèhófà, jọ̀ọ́ jẹ́ kí inú rẹ dùn sí ọrẹ ìyìn àtọkànwá mi.​—Sm. 119:108.

Ṣé àyà ẹ máa ń lù kìkì tó o bá fẹ́ nawọ́ nípàdé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ni irú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ wa lẹ̀rù máa ń bà déwọ̀n àyè kan tá a bá fẹ́ dáhùn. Ká sòótọ́, ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ fi hàn pé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ó fi hàn pé o gbà pé àwọn míì sàn jù ẹ́ lọ, Jèhófà sì fẹ́ràn àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. (Sm. 138:6; Fílí. 2:3) Àmọ́, Jèhófà fẹ́ kó o máa yin òun kó o sì máa gbé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ ró nípàdé. (1 Tẹs. 5:11) Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì máa fún ẹ nígboyà láti máa dáhùn. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Bíbélì kan. Bíbélì sọ pé gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe nínú ọ̀rọ̀ tá à ń sọ àti nínú bá a ṣe ń sọ ọ́. (Ják. 3:2) Torí náà, Jèhófà ò retí pé ká jẹ́ ẹni pípé, àwọn ará wa náà ò sì retí pé a máa jẹ́ bẹ́ẹ̀. (Sm. 103:​12-14) Ìdílé kan náà ni gbogbo wa, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Máàkù 10:​29, 30; Jòh. 13:35) Wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ìdáhùn wa máa bọ́ sójú ẹ̀ tán. w19.01 8 ¶3; 10-11 ¶10-11

Monday, December 7

Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nígbà ọ̀dọ́ rẹ.​—Oníw. 12:1.

Kò rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ayé yìí, àmọ́ ó ṣeé ṣe. Jèhófà fẹ́ kẹ́ ẹ gbádùn ìgbésí ayé yín, kẹ́ ẹ sì ṣàṣeyọrí. Tẹ́ ẹ bá gbára lé Jèhófà, ẹ máa ṣàṣeyọrí nísinsìnyí àti jálẹ̀ ìgbésí ayé yín. Kí ọ̀rọ̀ náà lè yé yín dáadáa, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ nínú bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gba Ilẹ̀ Ìlérí. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ àtiwọ Ilẹ̀ Ìlérí, Ọlọ́run ò sọ fún wọn pé kí wọ́n lọ kọ́ bí wọ́n ṣe ń jagun. (Diu. 28:​1, 2) Dípò bẹ́ẹ̀, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa pa àṣẹ òun mọ́ kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé òun. (Jóṣ. 1:​7-9) Lójú èèyàn, ó lè dà bíi pé ìmọ̀ràn yẹn ò mọ́gbọ́n dání. Àmọ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ nìyẹn torí pé léraléra ni Jèhófà jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì. (Jóṣ. 24:​11-13) Ó ṣe kedere pé kéèyàn tó lè ṣègbọràn sí Ọlọ́run, èèyàn gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́. Téèyàn bá ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run, kò ní rí ìjákulẹ̀ láé. Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí, kò sì yí pa dà títí dòní olónìí. w18.12 25 ¶3-4

Tuesday, December 8

Olúwa ọ̀dọ̀ ta la máa lọ? Ìwọ lo ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun. ​—Jòh. 6:68.

Lónìí, àwọn kan ti fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀ torí wọn ò fara mọ́ àwọn òye tuntun tó ń dé. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míì ti jẹ́ kí èrò àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn alátakò kó sí wọn lórí. Èyí ti mú kí àwọn kan dìídì fi Jèhófà àti ètò rẹ̀ sílẹ̀. (Héb. 3:​12-14) Báwo ni ò bá ṣe dùn tó ká ní wọ́n jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn fẹsẹ̀ múlẹ̀ tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jésù bí àpọ́sítélì Pétérù ti ṣe! Díẹ̀díẹ̀ làwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í fi òtítọ́ sílẹ̀ láìfura. Ṣe lọ̀rọ̀ wọn dà bí ọkọ̀ ojú omi kan tí omi rọra ń gbé lọ díẹ̀díẹ̀ kúrò ní etíkun. Bíbélì sọ pé ṣe ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń “sú lọ” kúrò nínú òtítọ́. (Héb. 2:1) Àwọn tó sú lọ yàtọ̀ sáwọn tó dìídì fi òtítọ́ sílẹ̀ torí pé wọn ò mọ̀ọ́mọ̀ fi òtítọ́ sílẹ̀, ṣe ni wọ́n máa ń ṣe ohun táá mú kí wọ́n jìnnà sí Jèhófà. Tí wọn ò bá sì ṣọ́ra, wọ́n á pàdánù àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà. w18.11 9 ¶5-6

Wednesday, December 9

Àwọn èèyàn rẹ máa yọ̀ǹda ara wọn tinútinú.​—Sm. 110:3.

Ǹjẹ́ wàá fẹ́ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kó o lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè gba fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, tí wọ́n sì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ló máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ yìí, èyí sì máa ń jẹ́ kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àwọn tó bá fẹ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ yìí gbọ́dọ̀ múra tán láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún wọn lẹ́yìn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà. Ǹjẹ́ ìwọ náà lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere kó o lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? (1 Kọ́r. 9:23) Torí pé a jẹ́ èèyàn Jèhófà, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń lawọ́ sáwọn èèyàn, a sì máa ń ṣe inúure sí wọn torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń láyọ̀, ọkàn wa sì balẹ̀. (Gál. 5:​22, 23) Ipò yòówù ká wà, tá a bá jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi ti Jèhófà, ó dájú pé a máa láyọ̀, àá sì jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n lójú rẹ̀!​—Òwe 3:​9, 10. w18.08 27 ¶16-18

Thursday, December 10

Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.​—Mát. 19:6.

Ẹnì kan lè béèrè pé, ‘Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé Kristẹni kan kò lè kọ ẹnì kejì rẹ̀ sílẹ̀ kó sì fẹ́ ẹlòmíì?’ Jésù sọ ojú tó fi wo ìkọ̀sílẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó ṣe panṣágà lòdì sí i, bí obìnrin kan, lẹ́yìn kíkọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, bá sì ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú òmíràn pẹ́nrẹ́n, ó ṣe panṣágà.” (Máàkù 10:​11, 12; Lúùkù 16:18) Ó ṣe kedere pé ojú pàtàkì ni Jésù fi wo ìgbéyàwó, irú ojú yìí kan náà ló sì fẹ́ káwọn míì fi wò ó. Tí ọkùnrin kan bá kọ ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ sílẹ̀ (tàbí tí obìnrin kan bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ láìṣẹ̀ láìrò) torí ẹ̀sùn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, tó wá lọ fẹ́ ẹlòmíì, àgbèrè ló ṣe. Òótọ́ sì lọ̀rọ̀ yìí, ti pé wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀ kò fòpin sí ìgbéyàwó náà. Lójú Ọlọ́run, wọ́n ṣì jẹ́ “ara kan.” Bákan náà, Jésù sọ pé tí ọkùnrin kan bá kọ ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ sílẹ̀, ó lè mú kí obìnrin náà ṣe àgbèrè. Lọ́nà wo? Láyé ìgbà yẹn, ó lè wu obìnrin kan tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ láti ní ọkọ míì torí àtirí owó gbọ́ bùkátà. Tírú obìnrin bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ ọkọ míì, àgbèrè ló ṣe. w18.12 11 ¶8-9

Friday, December 11

Ibi tí mo ti ń ṣe olùṣọ́ ni èmi yóò dúró sí.​—Háb. 2:1.

Ọ̀rọ̀ tí Hábákúkù bá Jèhófà sọ jẹ́ kọ́kàn rẹ̀ balẹ̀ gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi pinnu pé òun máa ní sùúrù títí dìgbà tí Jèhófà máa gbé ìgbésẹ̀. Kì í ṣe bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ lásìkò yẹn ló mú kó ṣèpinnu yìí, torí nígbà tó yá, ó tún sọ pé òun máa fi “ìdákẹ́jẹ́ẹ́ dúró de ọjọ́ wàhálà.” (Háb. 3:16) Kí la rí kọ́ látinú ìpinnu tí Hábákúkù ṣe yìí? Àkọ́kọ́, a ò gbọ́dọ̀ dákẹ́ àdúrà láìka àdánwò yòówù ká máa kojú. Ìkejì, a gbọ́dọ̀ máa tẹ́tí sí Jèhófà nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. Ìkẹta, a gbọ́dọ̀ fi sùúrù dúró de Jèhófà, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó máa yanjú àwọn ìṣòro wa lásìkò tó tọ́ lójú rẹ̀. Táwa náà bá ń tẹ́tí sí Jèhófà, tá à ń gbàdúrà déédéé, tá a sì ń fi sùúrù dúró dè é bíi ti Hábákúkù, ó dájú pé ọkàn wa máa balẹ̀, ìyẹn á sì jẹ́ ká lè fara da ìṣòro yòówù ká máa kojú. Ìrètí tá a ní máa jẹ́ ká ní sùúrù, ká sì máa láyọ̀ torí a mọ̀ pé Baba wa ọ̀run máa dá sí ọ̀rọ̀ náà láìpẹ́.​—Róòmù 12:12. w18.11 15-16 ¶11-12

Saturday, December 12

Kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tó bójú mu ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmọ̀wọ̀n ara ẹni àti àròjinlẹ̀.​—1 Tím. 2:9.

Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo mímú àwọn míì kọsẹ̀? Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí tí wọ́n gbà gbọ́ kọsẹ̀, yóò sàn fún un bí a bá gbé ọlọ irúfẹ́ èyí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí kọ́ ọrùn rẹ̀, kí a sì gbé e sọ sínú òkun ní ti gidi.” (Máàkù 9:42) Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé ọ̀ràn ńlá ni téèyàn bá mú àwọn míì kọsẹ̀. Níwọ̀n bí Jésù ti fìwà jọ Baba rẹ̀ láìkù síbì kan, ó dájú pé Jèhófà náà kórìíra kẹ́nì kan fi àìbìkítà hùwà tó máa mú kí ẹlòmíì kọsẹ̀. (Jòh. 14:9) Ṣé ojú tí Jèhófà àti Jésù fi ń wo mímú àwọn míì kọsẹ̀ làwa náà fi ń wò ó? Ṣé ó hàn nínú ìwà wa pé a ò fẹ́ mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, a lè nífẹ̀ẹ́ àtimáa wọ àwọn aṣọ kan tàbí múra láwọn ọ̀nà kan tó ṣeé ṣe kó máa kọ àwọn míì lóminú nínú ìjọ, ó sì lè jẹ́ pé irú aṣọ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ káwọn míì ro èròkerò. Ǹjẹ́ ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará máa mú ká yẹra fún wíwọ àwọn aṣọ bẹ́ẹ̀? w18.11 25 ¶9-10

Sunday, December 13

Sátánì bá dá Jèhófà lóhùn pé: “Ṣé lásán ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run ni? . . . Na ọwọ́ rẹ, kí o sì kọ lu gbogbo ohun tó ní, ó dájú pé ó máa bú ọ níṣojú rẹ gan-an.”​—Jóòbù 1:​9, 11.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa jẹ́ oníwà títọ́? Ìdí kan ni pé Sátánì parọ́ mọ́ Jèhófà, ó sì tún fẹ̀sùn kan àwa náà. Áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yẹn ba Jèhófà lórúkọ jẹ́, ó ní ìkà ni Jèhófà, onímọtara-ẹni-nìkan ni àti pé Alákòóso tí kì í sòótọ́ ni. Ó bani nínú jẹ́ pé Ádámù àti Éfà gba ohun tí Sátánì sọ gbọ́, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. (Jẹ́n. 3:​1-6) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ àǹfààní làwọn tọkọtaya yìí ní láti mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà túbọ̀ lágbára. Àmọ́ nígbà tí Sátánì dán wọn wò, ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà ti dín kù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jinlẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn wá gbé ìbéèrè kan dìde: Ǹjẹ́ ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí á lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà débi pé á jẹ́ adúróṣinṣin sí i lójú àdánwò? Lédè míì, ṣé àwa èèyàn lè jẹ́ oníwà títọ́? Ìbéèrè yìí ló jẹ yọ nígbà tí Jóòbù kojú àdánwò. (Jóòbù 1:​8-11) Aláìpé bíi tiwa ni, òun náà sì ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ torí pé ó máa ń hu ìwà tó tọ́. w19.02 3-4 ¶6-7

Monday, December 14

Ó . . . ta gbogbo ohun tó ní, ó sì rà á.​—Mát. 13:46.

Ká lè mọ bí òtítọ́ Bíbélì ti ṣeyebíye tó, Jésù ṣe àpèjúwe nípa ọkùnrin arìnrìn-àjò kan tó rí péálì àtàtà. Nígbà tí ọkùnrin náà rí péálì iyebíye kan, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló “ta gbogbo ohun tí ó ní,” ó sì rà á. (Mát. 13:​45, 46) Òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló dà bíi péálì yẹn. Nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn nǹkan míì látinú Bíbélì, a mọyì rẹ̀ débi pé tinútinú la fi yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kó má bàa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Tá a bá mọyì òtítọ́ yìí, a ò ní “tà á,” ìyẹn ni pé a ò ní fi tàfàlà láé. (Òwe 23:23) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn èèyàn Jèhófà ti jẹ́ kí òtítọ́ iyebíye yìí bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Ó dájú pé a ò ní jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa láé! Tá ò bá fẹ́ kí òtítọ́ yìí bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, pé ká máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòh. 2-4) Tá a bá fẹ́ máa rìn nínú òtítọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí òtítọ́ máa darí ìgbésí ayé wa. w18.11 9 ¶3

Tuesday, December 15

Ìgbàgbọ́ mú kí àwọn ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn èèyàn náà fi ọjọ́ méje yan yí ibẹ̀ ká.​—Héb. 11:30.

Jèhófà fún Jóṣúà ní ìtọ́ni pé wọn ò gbọ́dọ̀ kojú ìlú Jẹ́ríkò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní kí wọ́n rìn yí ká ìlú náà lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà, tó bá sì di ọjọ́ keje, kí wọ́n rìn yí ká ìlú náà lẹ́ẹ̀méje. Àwọn ọmọ ogun kan lè máa ronú pé, ‘Ìwọ̀nba okun tá a ní la tún fi ń ṣòfò yìí!’ Àmọ́ Jèhófà mọ ohun tó ń ṣe. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí fún ìgbàgbọ́ wọn lókun, kódà wọn ò tiẹ̀ kojú àwọn ọmọ ogun alágbára tó wà ní Jẹ́ríkò rárá. (Jóṣ. 6:​2-5) Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa? Nígbà míì, a lè má mọ ìdí tí ètò Ọlọ́run fi fún wa láwọn ìtọ́ni tuntun kan. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kó kọ́kọ́ rí bákan lára wa nígbà tí ètò Ọlọ́run sọ pé ká máa lo fóònù wa fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, ká sì máa lò ó lóde ẹ̀rí àti láwọn ìpàdé. Àmọ́ ní báyìí, ó ṣeé ṣe ká ti rí àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀. Bá a ṣe ń rí ìbùkún táwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ ń mú wá, ìgbàgbọ́ wa ń lágbára sí i, ìyẹn sì ń jẹ́ ká wà níṣọ̀kan. w18.10 23 ¶8-9

Wednesday, December 16

Olúwa, ṣé àkókò yìí lo máa dá ìjọba pa dà fún Ísírẹ́lì?​—Ìṣe 1:6.

Èrò táwọn Júù ní nípa mèsáyà náà làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní, èyí ló sì mú káwọn ará Gálílì pinnu láti fi Jésù jọba. Wọ́n rí i pé sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́ ni Jésù, ó lè mú àwọn aláìsàn lára dá, ó sì lè bọ́ àwọn tébi ń pa. Kódà ìgbà kan wà tó bọ́ àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000], torí náà wọ́n lè máa ronú pé táwọn bá fi Jésù jọba, ayé àwọn ti dáa nìyẹn. Bíbélì sọ pé: “Jésù, ní mímọ̀ pé wọ́n máa tó wá mú òun láti fi òun jẹ ọba, tún fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí òkè ńlá ní òun nìkan.” (Jòh. 6:​10-15) Nígbà tí ara àwọn èèyàn náà balẹ̀ díẹ̀ lọ́jọ́ kejì, Jésù lọ sí òdì kejì Òkun Gálílì, ó sì ṣàlàyé ìdí tóun fi wá sáyé fún wọn. Ó sọ pé kì í ṣe nǹkan tara ni òun wá pèsè fún wọn, bí kò ṣe láti kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó ní: “Ẹ ṣiṣẹ́, kì í ṣe fún oúnjẹ tí ń ṣègbé, bí kò ṣe fún oúnjẹ tí ó wà títí ìyè àìnípẹ̀kun.”​—Jòh. 6:​25-27. w18.06 4 ¶4-5

Thursday, December 17

Kò ní ṣẹ́ esùsú kankan tó ti fọ́, kò sì ní pa òwú àtùpà kankan tó ń jó lọ́úlọ́ú tí wọ́n fi ọ̀gbọ̀ ṣe. ​—Àìsá. 42:3.

Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an, ó sì máa ń gba tiwọn rò. Ó mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá, ìyẹn àwọn tó dà bí esùsú fífọ́ tàbí òwú àtùpà tó ń jó lọ́úlọ́ú, tó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán. Abájọ tí Jésù fi jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú, ẹni tó ń gba tàwọn míì rò, tó sì máa ń mú sùúrù fún wọn. (Máàkù 10:14) Òótọ́ ni pé òye tiwa kò tó ti Jésù, a ò sì lè mọ̀ọ̀yàn kọ́ bíi tiẹ̀. Síbẹ̀, ó yẹ ká máa gba tàwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa rò. Ìyẹn gba pé, ká mọ bó ṣe yẹ ká bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ìgbà tó yẹ ká lọ sọ́dọ̀ wọn àti bó ṣe yẹ ká pẹ́ tó lọ́dọ̀ wọn. Lónìí, àwọn oníṣòwò tí ò lójú àánú, àwọn jẹgúdújẹrá olóṣèlú àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí ò mọ̀ ju owó lọ ti fi ojú ọ̀pọ̀ èèyàn rí màbo, ó dà bí ìgbà tí wọ́n ti ‘bó wọn láwọ, tí wọ́n sì fọ́n wọn ká.’ (Mát. 9:36) Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ò fọkàn tán ẹnikẹ́ni, wọ́n ò sì nírètí. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì ká máa gba tiwọn rò, ká sì máa fohùn pẹ̀lẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀ tá a bá ń wàásù fún wọn! Ká sòótọ́, kì í ṣe torí pé a mọ Bíbélì tàbí a mọ bá a ṣe ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀ nìkan lọ̀pọ̀ ṣe ń tẹ́tí sí wa, ṣùgbọ́n wọ́n máa ń kíyè sí i bí ọ̀rọ̀ wọn ṣe máa ń jẹ wá lógún, tá a sì ń gba tiwọn rò. w18.09 31-32 ¶13-14

Friday, December 18

Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.​—Mát. 5:3.

Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a mọyì àwọn nǹkan tẹ̀mí, tá a sì ń fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa láyọ̀, ìyẹn sì máa jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. (Títù 2:13) Tá a bá fẹ́ ní ayọ̀ tó máa wà pẹ́ títí, ó ṣe pàtàkì ká ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú [Jèhófà] Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣe ni èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀!” (Fílí. 4:4) Torí náà, tá ò bá fẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́, a gbọ́dọ̀ máa fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣèwà hù. (Òwe 3:​13, 18) Tá ò bá fẹ́ kí ohunkóhun ba ayọ̀ wa jẹ́, kì í ṣe pé ká kàn ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan, ó tún ṣe pàtàkì ká fi í sílò. Jésù tẹnu mọ́ bí èyí ti ṣe pàtàkì tó nígbà tó sọ pé: “Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.” (Jòh. 13:17; Ják. 1:25) Tá a bá ń fi àwọn ohun tá à ń kọ́ sílò, a máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ayọ̀ wa sì máa wà pẹ́ títí. w18.09 18 ¶4-6

Saturday, December 19

Ìgbà gbogbo [ni Épáfírásì] ń gbàdúrà lójú méjèèjì nítorí yín. ​—Kól. 4:12.

Épáfírásì mọ àwọn ará dáadáa, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Épáfírásì náà ní àwọn ìṣòro tiẹ̀ torí pé Pọ́ọ̀lù pè é ní “òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi.” Síbẹ̀, ó máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ òun lọ́kàn. (Fílém. 23) Ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ran àwọn ará lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Ẹ ò rí i pé ànímọ́ àtàtà ni Epafírásì ní! Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa, kódà ká máa dárúkọ wọn nínú àdúrà wa torí pé Jèhófà máa ń gbọ́ irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀. (2 Kọ́r. 1:11; Ják. 5:16) Ẹ jẹ́ ká ronú nípa àwọn tá a lè forúkọ wọn sádùúrà. Bíi ti Épáfírásì, ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló máa ń gbàdúrà fáwọn ará ìjọ tó ń kojú àwọn ìṣòro tó le tàbí kí wọ́n gbàdúrà fáwọn ìdílé tó níṣòro àtijẹ-àtimu. Láfikún, ó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn téèyàn wọn kú tàbí àwọn tí ogun àtàwọn àjálù míì ṣẹlẹ̀ lágbègbè wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn míì tọ́rọ̀ àtijẹ-àtimu ṣòro fún. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló nílò àdúrà wa. w18.09 5-6 ¶12-13

Sunday, December 20

Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.​—Ìṣe 20:35.

Kì í ṣe àwọn nǹkan tara nìkan ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn àwọn nǹkan míì tún wà tá a lè fún àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, a lè fún àwọn míì ní ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ìṣe 20:​31-35) Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ lórí kókó yìí. Ohun tó sọ àti ohun tó ṣe jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa lo àkókò wa àti okun wa fáwọn míì, ká máa fìfẹ́ hàn sí wọn, ká sì máa tẹ́tí gbọ́ wọn. Àwọn kan tó máa ń ṣèwádìí nípa ìwà ẹ̀dá sọ pé àwọn tó bá ń fúnni máa láyọ̀. Àpilẹ̀kọ kan sọ pé àwọn èèyàn máa ń láyọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe ohun tó dáa fún àwọn míì. Kódà, àwọn olùṣèwádìí sọ pé téèyàn bá ń ran àwọn míì lọ́wọ́, ìgbésí ayé rẹ̀ á nítumọ̀. Ìdí nìyẹn táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan fi sọ pé ó dáa kéèyàn máa yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ìlú. Wọ́n sọ pé téèyàn bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á láyọ̀, ìlera ẹ̀ á sì túbọ̀ dáa sí i. Ohun tí wọ́n sọ yìí ò yà wá lẹ́nu torí pé ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa ti sọ nínú Bíbélì pé fífúnni máa ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀.​—2 Tím. 3:​16, 17. w18.08 22 ¶17-18

Monday, December 21

Ẹ yéé fi ìrísí òde ṣe ìdájọ́, àmọ́ ẹ máa dá ẹjọ́ òdodo.​—Jòh. 7:24.

Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fini lọ́kàn balẹ̀ nípa Jésù Kristi Olúwa wa. Ó sọ pé, Jésù ò ní “ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa “fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀.” (Aìsá. 11:​3, 4) Kí nìdí tí èyí fi fini lọ́kàn balẹ̀? Ìdí ni pé inú ayé tí ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti gbilẹ̀ táwọn èèyàn sì máa ń wojú ṣe nǹkan là ń gbé. Torí náà, gbogbo wa là ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Jésù tó jẹ́ Onídàájọ́ òdodo máa ṣèdájọ́, torí pé kì í ṣe ohun tó hàn sí ojú ló máa fi ṣèdájọ́! Onírúurú èrò la máa ń ní nípa àwọn míì. Àmọ́ torí pé a kì í ṣe ẹni pípé bíi Jésù, èrò wa nípa àwọn míì lè má dáa tó. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tá a rí ló máa ń pinnu ohun tá a máa rò nípa ẹnì kan. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó pàṣẹ fún wa pé, ká má ṣèdájọ́ “láti inú ìrísí òde,” ṣùgbọ́n ká “fi ìdájọ́ òdodo ṣèdájọ́.” Èyí fi hàn pé Jésù fẹ́ ká fara wé òun, ká má ṣe fi ìrísí pinnu irú ẹni téèyàn kan jẹ́. w18.08 8 ¶1-2

Tuesday, December 22

[Wàá] gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ pé, “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” ​—Àìsá. 30:21.

Òótọ́ ni pé Jèhófà kì í bá wa sọ̀rọ̀ ní tààràtà látọ̀run. Àmọ́, ó ń tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bákan náà, Jèhófà ń fi ẹ̀mí mímọ́ darí “ìríjú olóòótọ́ náà” láti máa fún àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ lóúnjẹ tẹ̀mí. (Lúùkù 12:42) Mélòó la fẹ́ kà nínú ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹrú yìí ń pèsè! Ṣé èyí tí wọ́n ń tẹ̀ sórí ìwé ni ká sọ ni, àbí èyí tó wà lórí ìkànnì, ká má tíì sọ tàwọn fídíò àtàwọn àtẹ́tísí lónírúurú. Ǹjẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì mú kó dá wa lójú pé kò sóhun tó kọjá agbára Jèhófà. Tó bá sì tó àsìkò, á ṣàtúnṣe sí gbogbo ohun tí Sátánì àti ayé yìí ti bà jẹ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé àá máa fetí sí ohùn Jèhófà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè fara da ìṣòro yòówù ká máa kojú nísinsìnyí àtèyí tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bíbélì sọ pé: “Ẹ nílò ìfaradà, pé lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ lè rí ohun tí ó ṣèlérí náà gbà.”​—Héb. 10:36. w19.03 13 ¶17-18

Wednesday, December 23

Jèhófà sọ fún Jóṣúà . . . pé: Mósè ìránṣẹ́ mi ti kú. Gbéra, kí o sọdá Jọ́dánì, ìwọ àti gbogbo èèyàn yìí.​—Jóṣ. 1:​1, 2.

Ọ̀pọ̀ ọdún ni Mósè fi jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, torí náà Jóṣúà lè máa ṣiyèméjì pé bóyá làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fọkàn tán òun, tí wọ́n á sì gbà pé òun ni aṣáájú wọn báyìí. (Diu. 34:​8, 10-12) Nígbà tí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa Jóṣúà 1:​1, 2, ó sọ pé: “Nígbà àtijọ́, ìlú kì í fara rọ lásìkò tí àkóso bá ti ọwọ́ ẹnì kan bọ́ sọ́wọ́ ẹlòmíì, bẹ́ẹ̀ náà ló sì rí títí dòní.” Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó máa gba irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tí àyà rẹ̀ ò ní já. Síbẹ̀, Jóṣúà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì gbé ìgbésẹ̀ akin lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tó di aṣáájú. (Jóṣ. 1:​9-11) Jèhófà náà ò sì já a kulẹ̀. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà lo áńgẹ́lì kan láti darí Jóṣúà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì dáàbò bò wọ́n. Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ náà ni áńgẹ́lì yẹn. (Ẹ́kís. 23:​20-23; Jòh. 1:1) Jèhófà ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ lásìkò tí nǹkan yí pa dà, ìyẹn lẹ́yìn tí Mósè kú tí Jóṣúà sì di aṣáájú. w18.10 22-23 ¶1-4

Thursday, December 24

Wọ́n sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀ torí àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà. ​—Mál. 3:16.

Jèhófà máa ń fojúure hàn sáwọn tó bá ń fínnúfíndọ̀ ṣe ìfẹ́ rẹ̀, á sì kọ orúkọ wọn sínú “ìwé ìrántí” rẹ̀. Ó láwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá ò bá fẹ́ kí Jèhófà yọ orúkọ wa kúrò nínú “ìwé ìrántí” rẹ̀. Málákì dìídì sọ pé a gbọ́dọ̀ ‘bẹ̀rù Jèhófà, ká sì máa ṣe àṣàrò lórí orúkọ rẹ̀.’ Tá a bá ń jọ́sìn ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun míì, èyí máa mú kí Jèhófà yọ orúkọ wa kúrò nínú ìwé ìyè lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. (Ẹ́kís. 32:33; Sm. 69:28) Ká ya ara wa sí mímọ́ kọjá ká kàn ṣèlérí fún Jèhófà pé àá máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ká sì ṣèrìbọmi. Ẹ̀ẹ̀kan la máa ń ṣe àwọn nǹkan yìí. Àmọ́, ìyàsímímọ́ wa gba pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà lójoojúmọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé wa.​—1 Pét. 4:​1, 2. w18.07 23-24 ¶7-9

Friday, December 25

Ní báyìí tí a ti kọjá àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ nípa Kristi, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ síwájú, ká dàgbà nípa tẹ̀mí.​—Héb. 6:1.

Ti pé a ti pẹ́ nínú òtítọ́ kò túmọ̀ sí pé òtítọ́ máa jinlẹ̀ lọ́kàn wa, a gbọ́dọ̀ máa “tẹ̀ síwájú.” Kí òtítọ́ tó lè jinlẹ̀ lọ́kàn wa, ìmọ̀ àti òye tá a ní gbọ́dọ̀ máa pọ̀ sí i. Ìdí nìyẹn tí ètò Ọlọ́run fi ń rọ̀ wá látìgbàdégbà pé ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. (Sm. 1:​1-3) Ṣé o ti pinnu láti máa ṣe bẹ́ẹ̀? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ lóye àwọn òfin àtàwọn ìlànà Jèhófà, ìmọ̀ rẹ á sì pọ̀ sí i. Òfin tó ṣe pàtàkì jù lọ táwa Kristẹni ń tẹ̀ lé ni òfin ìfẹ́. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:35) Jákọ́bù àbúrò Jésù pe ìfẹ́ ní “ọba òfin.” (Ják. 2:8) Pọ́ọ̀lù náà sọ pé: “Ìfẹ́ ni ìmúṣẹ òfin.” (Róòmù 13:10) Kò yà wá lẹ́nu pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an torí Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”​—1 Jòh. 4:8. w18.06 19 ¶14-15

Saturday, December 26

Wọ́n gbé ẹ̀mí rẹ̀ gbóná, ó sì fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ láìronú.​—Sm. 106:33.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ̀, Mósè lẹni tó ń bínú. Dípò kó kó ara rẹ̀ níjàánu, ṣe ló sọ̀rọ̀ láìronú nípa ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ. Mósè jẹ́ kí ohun táwọn míì ṣe pín ọkàn rẹ̀ níyà, kò sì wojú Jèhófà mọ́. Òótọ́ ni pé Mósè ṣe ohun tó tọ́ nígbà tí ọ̀rọ̀ yẹn kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀. (Ẹ́kís. 7:6) Àmọ́ bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, àìmọye ìgbà ni Mósè fara da ìwà ọ̀tẹ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì hù, ó ṣeé ṣe kéyìí ti mú kí nǹkan sú u, kára sì máa kan án. Ó tún lè jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ ló gbà á lọ́kàn dípò kó máa ronú nípa bó ṣe máa fògo fún Jèhófà. Tí irú wòlíì olóòótọ́ bíi Mósè bá lè ní ìpínyà ọkàn, kó sì kọsẹ̀, kò sí àní-àní pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà. Bíi ti Mósè, àwa náà ò ní pẹ́ wọ ilẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ kan, ìyẹn ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí. (2 Pét. 3:13) Ó dájú pé kò sẹ́ni tó máa fẹ́ kí irú àǹfààní yìí bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́. Àmọ́, tá ò bá fẹ́ kó bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà bá a ṣe ń wojú Jèhófà, a sì gbọ́dọ̀ máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nígbà gbogbo.​—1 Jòh. 2:17. w18.07 15 ¶14-16

Sunday, December 27

Ẹ sì ti ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.​—1 Jòh. 2:14.

Sátánì ò lè fipá mú ká ṣe ohun tí kò wù wá. (Ják. 1:14) Àmọ́ torí àìmọ̀kan, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe ohun tí Sátánì fẹ́ láìmọ̀. Tẹ́nì kan bá wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, òun fúnra rẹ̀ á pinnu bóyá ohun tí Sátánì fẹ́ lòun máa ṣe tàbí ohun tí Jèhófà fẹ́. (Ìṣe 3:17; 17:30) Tá a bá pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ la máa ṣe, kò sí ohun tí Sátánì lè ṣe táá mú ká yẹsẹ̀. (Jóòbù 2:3; 27:5) Àwọn nǹkan míì wà tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ò lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kò síbì kankan tí Bíbélì ti sọ pé wọ́n lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Jèhófà àti Jésù nìkan ni Bíbélì sọ pé wọ́n ní agbára yẹn. (1 Sám. 16:7; Máàkù 2:8) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ó dá wa lójú pé bí Èṣù tiẹ̀ pa wá lára, Jèhófà ò ní jẹ́ kó ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. (Sm. 34:7) Ó yẹ ká mọ ọ̀tá wa, àmọ́ kò sídìí tó fi yẹ ká bẹ̀rù rẹ̀. Lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà, àwa èèyàn aláìpé lè ṣẹ́gun Sátánì. Tá a bá kọjú ìjà sí Èṣù, ó dájú pé ó máa sá kúrò lọ́dọ̀ wa.​—Ják. 4:7; 1 Pét. 5:9. w18.05 26 ¶15-17

Monday, December 28

Fi gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lé Jèhófà lọ́wọ́, ohun tí o fẹ́ ṣe á sì yọrí sí rere.​—Òwe 16:3.

Jẹ́ ká sọ pé o fẹ́ lọ síbi ayẹyẹ pàtàkì kan, ibẹ̀ jìnnà gan-an, o sì gbọ́dọ̀ wọkọ̀ kó o tó débẹ̀. Nígbà tó o dé ibùdókọ̀, o bá èrò rẹpẹtẹ táwọn náà fẹ́ rìnrìn-àjò, bẹ́ẹ̀ làwọn onímọ́tò ń pe onírúurú ibi tí wọ́n ń lọ, ìyẹn wá mú kí nǹkan tojú sú ẹ. Ṣé wàá kàn bọ́ sínú mọ́tò kan láìbéèrè ibi tó ń lọ? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ibòmíì ló máa gbé ẹ lọ. Àwọn ọ̀dọ́ ló dà bí àwọn tó wà ní ibùdókọ̀ tí wọ́n ń rìnrìn-àjò yẹn. Bí ìrìn-àjò ni ìgbésí ayé rí, ìrìn-àjò náà sì jìnnà gan-an. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn ọ̀dọ́ lè fi ìgbésí ayé wọn ṣe, ìyẹn sì lè mú kí nǹkan tojú sú wọn nígbà míì. Torí náà ẹ̀yin ọ̀dọ́, ohun tó dáa jù ni pé kẹ́ ẹ mọ ibi tẹ́ ẹ fẹ́ forí lé nígbèésí ayé yín. Ṣé ẹ̀yin ọ̀dọ́ máa fi ìgbésí ayé yín sin Jèhófà? Ìyẹn gba pé kẹ́ ẹ fi Jèhófà sọ́kàn nígbà tẹ́ ẹ bá fẹ́ pinnu bó ṣe yẹ kẹ́ ẹ kàwé tó, irú iṣẹ́ tẹ́ ẹ máa ṣe, ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, ọmọ bíbí àtàwọn nǹkan míì. Ó tún gba pé kẹ́ ẹ láwọn àfojúsùn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún àwọn ọ̀dọ́ tó bá fayé wọn sìn ín, ayé wọn á sì dùn bí oyin. w18.04 25 ¶1-3

Tuesday, December 29

Áà, ọmọbìnrin mi! O ti mú kí ọkàn mi bà jẹ́, torí ìwọ ni ẹni tí màá ní kó lọ. ​—Oníd. 11:35.

Jẹ́fútà mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ, ó rán ọmọbìnrin rẹ̀ lọ sí Ṣílò kó lè lọ sìn jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (Oníd. 11:​30-35) Ká sòótọ́, ìpinnu yìí ò rọrùn rárá fún Jẹ́fútà, síbẹ̀ ó dájú pé ó máa nira jùyẹn lọ fún ọmọ rẹ̀. (Oníd. 11:​36, 37) Ìdí ni pé kò ní lọ́kọ, kò sì ní bímọ, ìyẹn túmọ̀ sí pé ibi tí orúkọ ìdílé wọn máa pa rẹ́ sí nìyẹn. Ṣé ẹ̀yin náà rí i pé ọmọbìnrin Jẹ́fútà nílò ìtùnú àti ìṣírí? Bíbélì sọ pé: “Ó sì wá jẹ́ ìlànà ní Ísírẹ́lì pé: Láti ọdún dé ọdún, àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì á lọ láti gbóríyìn fún ọmọbìnrin Jẹ́fútà tí í ṣe ọmọ Gílíádì, ní ọjọ́ mẹ́rin lọ́dún.” (Oníd. 11:​39, 40) Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọn kò tíì ṣègbéyàwó torí kí wọ́n lè gbájú mọ́ “àwọn ohun ti Olúwa”?​—1 Kọ́r. 7:​32-35. w18.04 17 ¶10-11

Wednesday, December 30

Àwọn áńgẹ́lì . . . fi ipò wọn àti ibi tó yẹ kí wọ́n máa gbé sílẹ̀. ​—Júùdù 6.

Àwọn áńgẹ́lì kan ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Sátánì. Ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, Sátánì tan àwọn áńgẹ́lì kan láti bá àwọn ọmọbìnrin èèyàn ṣèṣekúṣe. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà tó sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ pé dírágónì náà wọ́ ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run pẹ̀lú rẹ̀. (Jẹ́n. 6:​1-4; Ìṣí. 12:​3, 4) Àwọn áńgẹ́lì yìí fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì gbà kí Sátánì máa darí àwọn. Kì í ṣe pé àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí kàn ń rìn kiri bí aláìníṣẹ́ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí Jèhófà ṣe gbé Ìjọba ọ̀run kalẹ̀ náà ni Sátánì gbé ìjọba tiẹ̀ náà kalẹ̀. Sátánì fúnra rẹ̀ ló ń darí ìjọba rẹ̀, ó sì ṣètò àwọn ẹ̀mí èṣù sí ìjọba ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó fún wọn ní ọlá àṣẹ, ó sì sọ wọ́n di alákòóso ayé. (Éfé. 6:12) Sátánì ń fi ìjọba tó gbé kalẹ̀ yìí darí ìjọba èèyàn. w18.05 23 ¶5-6

Thursday, December 31

Màá yin Jèhófà, ẹni tó fún mi ní ìmọ̀ràn. Kódà láàárín òru, èrò inú mi ń tọ́ mi sọ́nà. ​—Sm. 16:7.

Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa máa ń jẹ́ kó bá wa wí nígbà míì. Dáfídì mọyì ìbáwí tí Jèhófà fún un. Ó máa ń ronú lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì ń jẹ́ kó máa darí òun. Tíwọ náà bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á sì máa wù ẹ́ pé kó o máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ nígbà gbogbo. Ìyẹn á mú kó o di ẹni tẹ̀mí, kí òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú rẹ. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Christin sọ pé: “Tí mo bá ń ṣèwádìí, tí mo sì ń ronú lórí ohun tí mo kà, ó máa ń ṣe mí bíi pé èmi gangan ni Jèhófà kọ ọ̀rọ̀ yìí fún!” Tó o bá jẹ́ ẹni tẹ̀mí, wàá rí i pé kò sí nǹkan kan mọ́ nínú ayé yìí, wàá sì tún mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáyé yìí láìpẹ́. Jèhófà ló dìídì fún ẹ ní ìmọ̀ àti òye yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó fẹ́ kó o gbájú mọ́ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, kó o ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, kọ́kàn ẹ sì balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.​—Aísá. 26:3. w18.12 26 ¶9-10

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́