ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es21 ojú ìwé 7-17
  • January

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • January
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Friday, January 1
  • Saturday, January 2
  • Sunday, January 3
  • Monday, January 4
  • Tuesday, January 5
  • Wednesday, January 6
  • Thursday, January 7
  • Friday, January 8
  • Saturday, January 9
  • Sunday, January 10
  • Monday, January 11
  • Tuesday, January 12
  • Wednesday, January 13
  • Thursday, January 14
  • Friday, January 15
  • Saturday, January 16
  • Sunday, January 17
  • Monday, January 18
  • Tuesday, January 19
  • Wednesday, January 20
  • Thursday, January 21
  • Friday, January 22
  • Saturday, January 23
  • Sunday, January 24
  • Monday, January 25
  • Tuesday, January 26
  • Wednesday, January 27
  • Thursday, January 28
  • Friday, January 29
  • Saturday, January 30
  • Sunday, January 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2021
es21 ojú ìwé 7-17

January

Friday, January 1

Ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.​—Mát. 28:19.

Ó máa ń wu gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run pé ká mọ bá a ṣe lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa “láìkù síbì kan.” (2 Tím. 4:5) Ó ṣe tán, kò sí iṣẹ́ míì tó ṣe pàtàkì, tó ń fúnni láyọ̀, tó sì tún jẹ́ kánjúkánjú bí iṣẹ́ ìwàásù. Bó ti wù kó rí, kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti lo ara wa lẹ́nu iṣẹ́ náà bá a ṣe fẹ́. Àwọn ojúṣe pàtàkì míì wà tó máa ń gba àkókò àti okun wa. Bí àpẹẹrẹ, ká lè bójú tó ara wa àti ìdílé wa, ó di dandan pé ká ṣiṣẹ́, èyí sì lè gba ọ̀pọ̀ wákàtí lójoojúmọ́. Yàtọ̀ síyẹn, bùkátà táwọn míì ń gbé nínú ìdílé kọjá kèrémí, àwọn kan ń ṣàìsàn, ìrẹ̀wẹ̀sì nìṣòro àwọn míì, nígbà táwọn àgbàlagbà ń bá hẹ́gẹhẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó fà á. Ká má ṣe rẹ̀wẹ̀sì bí àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra kò bá jẹ́ ká lè ṣe tó bó ṣe wù wá lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Jésù mọ̀ pé ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run á yàtọ̀ síra. (Mát. 13:23) Jèhófà mọyì gbogbo ohun tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé gbogbo ohun tágbára wa gbé la ṣe.​—Héb. 6:​10-12. w19.04 2 ¶1-3

Saturday, January 2

Òpùrọ́ ni [Èṣù], òun sì ni baba irọ́.​—Jòh. 8:44.

Àwọn irọ́ Sátánì tàbùkù sí Jèhófà. Lára àwọn irọ́ náà ni pé àwọn òkú máa ń joró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Ẹ wo bí ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe tàbùkù sí orúkọ Ọlọ́run! Lọ́nà wo? Ńṣe ni ẹ̀kọ́ burúkú yìí ń jẹ́ kó dà bíi pé Jèhófà fìwà jọ Sátánì tó jẹ́ ìkà, bẹ́ẹ̀ sì rèé, Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà. (1 Jòh. 4:8) Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára rẹ? Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà? Pàápàá tá a bá rántí pé Jèhófà kórìíra ìwà ìkà. (Jer. 19:5) Àwọn irọ́ Sátánì mú kó dà bíi pé ẹbọ ìràpadà Kristi kò wúlò. (Mát. 20:28) Irọ́ míì tí Sátánì pa ni pé ọkàn àwọn èèyàn kì í kú. Tó bá jẹ́ òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn, á jẹ́ pé wọ́n ti ní ìyè àìnípẹ̀kun nìyẹn. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kò sídìí tí Kristi fi ní láti kú fún wa ká lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ má sì gbàgbé pé ìràpadà Kristi ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí Ọlọ́run àti Jésù gbà fi ìfẹ́ hàn sí wa. (Jòh. 3:16; 15:13) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Jèhófà àti Jésù bí ẹ̀kọ́ èké yẹn ṣe mú kó dà bíi pé wọ́n kàn fi ẹ̀bùn iyebíye yìí ṣòfò! w19.04 14 ¶1; 16 ¶8-9

Sunday, January 3

“Ta ló ti wá mọ èrò inú Jèhófà, kí ó lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́?” Àmọ́ àwa ní èrò inú Kristi.​—1 Kọ́r. 2:16.

Ibo la ti lè rí àwọn ohun tí Jésù fi kọ́ni? Àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí Jésù fi kọ́ni àtohun tó ṣe nígbà tó wà láyé. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìwé tó kù nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì náà tún jẹ́ ká mọ èrò Kristi. Ó ṣe tán, àwọn tó ní “èrò inú Kristi” ló kọ àwọn ìwé náà, ẹ̀mí mímọ́ ló sì darí wọn. Gbogbo apá ìgbésí ayé wa la ti lè fi ẹ̀kọ́ Jésù sílò. Torí náà, òfin Kristi kan ohun tá à ń ṣe nínú ilé, níbi iṣẹ́, nílé ìwé àti nínú ìjọ. (Gál. 6:2) Ká lè dojúlùmọ̀ òfin yìí, ó ṣe pàtàkì ká máa ka Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. A lè fi hàn pé à ń tẹ̀ lé òfin yìí tá a bá ń fi àwọn ìtọ́ni àtàwọn ìlànà inú rẹ̀ sílò nígbèésí ayé wa, tá a sì ń pa àwọn àṣẹ Jésù mọ́. Tá a bá ń pa òfin Kristi mọ́, Jèhófà là ń ṣègbọràn sí torí pé Òun ni orísun gbogbo nǹkan tí Jésù fi kọ́ni.​—Jòh. 8:28. w19.05 3 ¶6-7

Monday, January 4

Àwọn èèyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà á máa burú sí i.​—2 Tím. 3:13.

Ó yani lẹ́nu pé àwọn kan ń hùwà tó ń múnú Sátánì dùn, èyí sì bani nínú jẹ́ gan-an. Àmọ́, gbogbo ohun tí Sátánì ń ṣe pátápátá ni Jèhófà ń rí, gbogbo ẹ̀dùn ọkàn wa ló mọ̀, á sì tù wá nínú. A mà dúpẹ́ o pé Ọlọ́run tá à ń sìn jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tó ń tù wá nínú nínú gbogbo àdánwò wa, kí a lè fi ìtùnú tí a gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ tu àwọn míì nínú lábẹ́ àdánwò èyíkéyìí tí wọ́n bá wà.” (2 Kọ́r. 1:​3, 4) Àwọn tí òbí ti pa tì àtàwọn tí mọ̀lẹ́bí tàbí ẹlòmíì ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé máa ń nílò ìtùnú gan-an. Onísáàmù náà Dáfídì mọ̀ pé kò sẹ́ni tó lè tuni nínú bíi Jèhófà. (Sm. 27:10) Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà máa ń bójú tó gbogbo àwọn táwọn èèyàn wọn pa tì. Lọ́nà wo? Ó máa ń lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, ó ṣe tán ìdílé kan ni gbogbo àwa tá à ń sin Jèhófà. Jésù jẹ́ kí èyí ṣe kedere nígbà tó pe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní arákùnrin, arábìnrin àti ìyá rẹ̀.​—Mát. 12:​48-50. w19.05 15-16 ¶8-9

Tuesday, January 5

Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.​—Fílí. 1:10.

Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká fi sípò àkọ́kọ́? Ó ṣe pàtàkì ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́. Àwọn orí Bíbélì tá à ń gbé yẹ̀ wò nípàdé àárín ọ̀sẹ̀ ti dín kù báyìí ká lè ṣàṣàrò lórí ẹ̀ ká sì lè ṣèwádìí nípa ẹ̀. Kì í ṣe bá a ṣe máa ka gbogbo ẹsẹ Bíbélì náà ló yẹ kó jẹ wá lógún, bí kò ṣe bí ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ ṣe máa wọ̀ wá lọ́kàn táá sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Sm. 19:14) Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye Bíbélì. Torí náà, fiyè sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀ pàápàá èyí tí wọ́n tọ́ka sí pé kí a kà nípàdé. Kíyè sí bí àwọn ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn kan nínú Ìwé Mímọ́ náà ṣe tan mọ́ kókó tá à ń jíròrò nínú àpilẹ̀kọ náà. Yàtọ̀ síyẹn, ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o kà, kó o sì ronú lórí bó o ṣe lè fi wọ́n sílò nígbèésí ayé rẹ.​—Jóṣ. 1:8. w19.05 27 ¶5; 28 ¶9

Wednesday, January 6

Oúnjẹ mi ni pé kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi, kí n sì parí iṣẹ́ rẹ̀.​—Jòh. 4:34.

Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù Kristi tó bá di pé ká fọwọ́ gidi mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Bó ṣe máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn ló kà sí pàtàkì jù nígbà tó wà láyé. Ó máa ń fẹsẹ̀ rìn lọ síbi tó jìnnà gan-an kó lè wàásù fáwọn èèyàn. Kò síbi tó ti bá àwọn èèyàn pàdé tí kì í bá wọn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ì báà jẹ́ ní gbangba tàbí nínú ilé. Ó ṣe kedere pé iṣẹ́ ìwàásù ló gbawájú nígbèésí ayé Jésù. A lè fara wé Jésù tá a bá ń wọ́nà láti wàásù fáwọn èèyàn níbikíbi tá a bá wà. Ó yẹ ká ṣe tán láti fàwọn nǹkan du ara wa ká lè túbọ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Máàkù 6:​31-34; 1 Pét. 2:21) Àwọn ará wa kan ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míì sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé tàbí olùrànlọ́wọ́. Àwọn kan ti kọ́ èdè míì, àwọn míì sì ti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Àmọ́, àwọn akéde ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, síbẹ̀ wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn. Ohun kan ni pé, Jèhófà ò retí pé ká ṣe ju agbára wa lọ. w19.04 4 ¶7-8

Thursday, January 7

Kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi máa múnú rẹ dùn, Jèhófà.​—Sm. 19:14.

Bi ara rẹ pé: ‘Nínú ọkàn mi lọ́hùn-ún, ṣé mi ò kì í jowú tàbí ṣe ìlara àwọn míì?’ (1 Pét. 2:1) ‘Ṣé mi ò kì í gbéra ga nítorí ibi tí mo dàgbà sí, bí mo ṣe kàwé tó tàbí torí bí mo ṣe lówó tó?’ (Òwe 16:5) ‘Ṣé mi ò kì í fojú pa àwọn míì rẹ́ torí pé wọn ò ní àwọn nǹkan tí mo ní tàbí torí ìlú tí wọ́n ti wá?’ (Jém. 2:​2-4) ‘Ṣé àwọn nǹkan tí ayé Sátánì ń gbé lárugẹ kò máa wọ̀ mí lójú?’ (1 Jòh. 2:​15-17) ‘Ṣé àwọn fíìmù tàbí géèmù tó ní ìṣekúṣe àti ìwà ipá ló máa ń wù mí?’ (Sm. 97:10; 101:3; Émọ́sì 5:15) Tá a bá lè wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, ó ṣeé ṣe ká rí àwọn ibi tó ti yẹ ká ṣàtúnṣe. Àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ lè nípa lórí wa, ó ṣe tán wọ́n máa ń sọ pé fi ọ̀rẹ́ rẹ hàn mí, kí n lè sọ irú ẹni tó o jẹ́. (Òwe 13:20) Èrò ayé Sátánì ni ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn tá a jọ wà nílé ìwé sábà máa ń gbé lárugẹ. Àmọ́, àwọn ọ̀rẹ́ gidi ló wà nínú ìjọ wa. Torí náà, inú ìjọ la ti lè rí àwọn táá mú kó máa wù wá “láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere.”​—Héb. 10:​24, 25, àlàyé ìsàlẹ̀. w19.06 12 ¶13-14

Friday, January 8

Ẹwà ló .  . . jẹ́ fún un pé kó gbójú fo àṣìṣe.​—Òwe 19:11.

Jèhófà dá wa ká lè máa gbádùn ni, kì í ṣe ká máa jìyà. Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu tí ìránṣẹ́ Jèhófà kan bá ń sọ̀rọ̀ láìronú torí àwọn ìṣòro tó dé bá a. (Jóòbù 6:​2, 3) Kódà tẹ́ni náà bá sọ àwọn nǹkan tí kò tọ́ nípa Jèhófà tàbí nípa wa, kò yẹ ká bínú sí i tàbí ká dá a lẹ́bi torí ohun tó sọ. Nígbà míì, ó lè gba pé ká tún èrò ẹnì kan tó ní ìdààmú ọkàn ṣe tàbí ká fìfẹ́ bá a wí. (Gál. 6:1) Ọ̀nà wo làwọn alàgbà lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Á dáa kí wọ́n fara wé Élíhù tó fara balẹ̀ tẹ́tí sí Jóòbù kó lè mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀. (Jóòbù 33:​6, 7) Ẹ̀yìn tí Élíhù lóye Jóòbù dáadáa ló tó fún un nímọ̀ràn tó tún èrò rẹ̀ ṣe. Bíi ti Élíhù, ó ṣe pàtàkì káwọn alàgbà fara balẹ̀ tẹ́tí sí ẹni tó ní ìdààmú ọkàn kí wọ́n lè lóye bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀. Tí wọ́n bá wá fún ẹni náà nímọ̀ràn, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ wọn wọ̀ ọ́ lọ́kàn. w19.06 22-23 ¶10-11

Saturday, January 9

Ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.​—Ìṣe 5:29.

Báwo ni wàá ṣe máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa? Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa fún àwọn alàgbà ìjọ ní ìtọ́sọ́nà, wọ́n á sì fún wọn láwọn àbá nípa bá a ṣe lè máa rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà, bá a ṣe lè máa pàdé pọ̀ láti jọ́sìn Jèhófà àti bá a ṣe lè máa wàásù ìhìn rere. Tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ̀ka ọ́fíìsì láti kàn sí àwọn alàgbà, àwọn alàgbà máa ṣèrànwọ́ tó yẹ fún ìwọ àti gbogbo àwọn ará tó wà nínú ìjọ kẹ́ ẹ lè máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó. Wọ́n á lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtọ́ni tó wà nínú ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run láti tọ́ yín sọ́nà. (Mát. 28:​19, 20; Héb. 10:​24, 25) Jèhófà ṣèlérí pé ìgbà gbogbo làwọn ìránṣẹ́ òun á máa rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà. (Àìsá. 65:​13, 14; Lúùkù 12:​42-44) Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ètò Ọlọ́run á ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kó o lè rí ìtìlẹ́yìn nípa tẹ̀mí gbà. Àmọ́ ohun kan wà tó yẹ kí ìwọ náà ṣe. Kí lohun náà? Tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa, rí i pé o wá ibi tó pa mọ́ dáadáa tó o lè tọ́jú Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde rẹ sí. Rí i dájú pé o ò kó àwọn nǹkan tó ṣeyebíye yìí síbi tí àwọn míì ti lè rí i, yálà èyí tí wọ́n tẹ̀ sórí ìwé tàbí èyí tó wà lórí ẹ̀rọ. Ó yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti rí i pé ìgbàgbọ́ òun lágbára. w19.07 10 ¶10-11

Sunday, January 10

Mo ti di ohun gbogbo nítorí gbogbo èèyàn, kí n lè gba àwọn kan là ní gbogbo ọ̀nà tí mo bá lè gbé e gbà.​—1 Kọ́r. 9:22.

Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe ẹ̀sìn kan tàbí òmíì. Àmọ́ láti bí ọdún mélòó kan báyìí, wọ́n ti ń yí èrò wọn pa dà nípa ẹ̀sìn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò ṣe ẹ̀sìn kankan mọ́. Kódà láwọn orílẹ̀-èdè kan, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn ibẹ̀ máa ń sọ pé àwọn ò ní ẹ̀sìn tàbí pé àwọn ò gba Ọlọ́run gbọ́. (Mát. 24:12) Kí nìdí táwọn tí ò ṣe ẹ̀sìn kankan fi túbọ̀ ń pọ̀ sí i? Ìgbádùn tàbí àníyàn ìgbésí ayé ló fà á fún àwọn kan. (Lúùkù 8:14) Àwọn kan tiẹ̀ wà tó sọ pé kò sí Ọlọ́run. Àwọn míì ní tiwọn gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ wọ́n gbà pé kò sí àǹfààní kankan nínú ẹ̀sìn, pé kò bá ọgbọ́n tàbí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu, bẹ́ẹ̀ ni kò bóde mu mọ́. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n gbọ́ tí àwọn ọ̀rẹ́, àwọn olùkọ́ tàbí àwọn oníròyìn máa sọ pé kò sẹ́ni tó ṣẹ̀dá àwọn nǹkan tó wà láyé, pé ṣe ni wọ́n ṣàdédé wà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọ́n lè má rí àwọn táá jẹ́ kí wọ́n rídìí tó fi yẹ kí wọ́n gba Ọlọ́run gbọ́. Ohun tó mú kọ́rọ̀ ẹ̀sìn sú àwọn míì ni ìwàkiwà tó kún ọwọ́ àwọn olórí ẹ̀sìn àti bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ owó, tí wọ́n sì ń ṣi agbára wọn lò. Láwọn ilẹ̀ kan, ìjọba ò fàyè gba káwọn ẹlẹ́sìn máa jọ́sìn Ọlọ́run fàlàlà. w19.07 20 ¶1-2

Monday, January 11

Ẹ dúró gbọn-in, ẹ má yẹsẹ̀, kí ẹ máa ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, kí ẹ sì mọ̀ pé làálàá yín kò ní já sí asán nínú Olúwa.​—1 Kọ́r. 15:58.

Kò dìgbà tára wa bá ń ta kébékébé ká tó lè tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kódà, àwọn tára wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbé kánkán mọ́ ṣì máa ń nítara, wọ́n sì máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (2 Kọ́r. 4:16) Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ṣùgbọ́n ní báyìí, àìlera ò jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, má banú jẹ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó o ti ṣe sẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Héb. 6:10) Torí náà, fi sọ́kàn pé kò dìgbà tó o bá ṣe ohun tó pọ̀ kó o tó lè fi hàn pé tọkàntọkàn lo fi ń sin Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, tó o bá ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ gbé, tó o sì lẹ́mìí tó dáa, ìyẹn á fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Kól. 3:23) Jèhófà mọ ohun tágbára wa gbé, kì í sì í béèrè ohun tó ju agbára wa lọ.​—Máàkù 12:​43, 44. w19.08 3 ¶6; 5 ¶11-12

Tuesday, January 12

Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ rere yín.​—Mát. 5:16.

Jèhófà máa ń lo “iṣẹ́ rere” àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti fa àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Mát. 5:​14, 15; 1 Pét. 2:12) Tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ kì í bá ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣé ó mọ èyíkéyìí lára àwọn ará ìjọ rẹ? O lè ní kó tẹ̀ lé ẹ lọ sípàdé. (1 Kọ́r. 14:​24, 25) Ó wù wá pé káwọn mọ̀lẹ́bí wa mọ Jèhófà, kí wọ́n sì jọ́sìn rẹ̀. Síbẹ̀, láìka bá a ṣe sapá tó, àwọn kan lè má wá. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má dá ara ẹ lẹ́bi. Ó ṣe tán, a ò lè fipá mú ẹnikẹ́ni di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó ti wù kó rí, táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ bá ń rí bó o ṣe ń láyọ̀, ó máa nípa rere lórí wọn. Torí náà, máa gbàdúrà fún wọn. Máa fi sùúrù bá wọn sọ̀rọ̀. Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ láé, má sì ronú pé wọn ò lè yí pa dà! (Ìṣe 20:20) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa bù kún gbogbo ìsapá ẹ. Táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ bá sì fetí sí ẹ, wọ́n máa rí ìgbàlà! w19.08 18-19 ¶15-17

Wednesday, January 13

Ojú ni fìtílà ara. Tí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan, gbogbo ara rẹ máa mọ́lẹ̀ yòò.​—Mát. 6:22.

Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Ohun tó ń sọ ni pé ó yẹ ká jẹ́ kí nǹkan ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, ká má ṣe máa lé tibí tọ̀hún, ká sì rí i pé a pọkàn pọ̀ sórí nǹkan tẹ̀mí. Jésù fúnra ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní ti pé ó pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ni kó gbawájú láyé wọn. Ẹ jẹ́ ká fara wé Jésù, ká pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ká máa “wá Ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́.” (Mát. 6:33) Ká lè túbọ̀ pọkàn pọ̀ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, á dáa ká dín àkókò tá à ń lò fáwọn nǹkan míì kù. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá ní àkókò tó pọ̀ sí i láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà, kí wọ́n sì wá jọ́sìn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ṣé a lè dín àkókò tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa kù ká lè túbọ̀ máa kópa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù láàárín ọ̀sẹ̀? Ohun míì tá a lè ṣe ni pé ká dín àkókò tá à ń lò nídìí eré ìnàjú kù. w19.04 5-6 ¶12-13

Thursday, January 14

Ibi gíga àti ibi mímọ́ ni mò ń gbé, àmọ́ mo tún ń gbé pẹ̀lú àwọn tí a tẹ̀ rẹ́, tí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí.​—Àìsá. 57:15.

Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni ètò Ọlọ́run ti yí iṣẹ́ wọn pa dà. Kò rọrùn fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí láti mú ara wọn bá ìyípadà náà mu. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn kan ti wà lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, wọ́n sì gbádùn ẹ̀ gan-an. Torí náà, kò rọrùn rárá fún wọn láti kọ́fẹ pa dà lẹ́yìn tí wọ́n fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, iṣẹ́ tuntun tí wọ́n gbà mọ́ wọn lára. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Ohun pàtàkì tó ràn wọ́n lọ́wọ́ ni ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà làwọn ya ara wọn sí mímọ́ fún, kì í ṣe fún iṣẹ́ kan tàbí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan. (Kól. 3:23) Inú wọn sì ń dùn láti máa fìrẹ̀lẹ̀ sin Jèhófà nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá gbà. Ṣe ni wọ́n “kó gbogbo àníyàn [wọn] lọ sọ́dọ̀” Jèhófà, torí ó dá wọn lójú pé á bójú tó wọn. (1 Pét. 5:​6, 7) A mà dúpẹ́ o pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, àá ṣe ara wa láǹfààní, àá sì ṣe àwọn míì náà láǹfààní. Yàtọ̀ síyẹn, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, á mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run. w19.09 6-7 ¶15-17

Friday, January 15

Àwọn ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà jẹ́ òdodo, wọ́n ń mú ọkàn yọ̀; . . . èrè ńlá wà nínú pípa wọ́n mọ́.​—Sm. 19:​8, 11.

Kì í ṣe pé Dáfídì jẹ́ olórí ìdílé nìkan, Jèhófà tún fi í ṣe olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Agbára wà lọ́wọ́ Dáfídì lóòótọ́ torí pé ọba ni. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tó ṣi agbára náà lò, ìyẹn sì mú kó ṣàṣìṣe. (2 Sám. 11:​14, 15) Àmọ́, ó rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, ó sì gba ìbáwí Jèhófà. Ó gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà, ó sì sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe dùn ún tó. Lẹ́yìn náà, ó sapá láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà. (Sm. 51:​1-4) Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní mú kó gba ìmọ̀ràn táwọn míì fún un títí kan àwọn obìnrin. (1 Sám. 19:​11, 12; 25:​32, 33) Dáfídì kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe rẹ̀, ó sì rí i pé ìjọsìn Jèhófà ló gbawájú láyé òun. Ọba Dáfídì mọ àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa fi ara rẹ̀ sábẹ́ Jèhófà. Lónìí, ṣe ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ Jèhófà àtàwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀ túbọ̀ ṣe kedere. Àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ Jèhófà ń “kígbe ayọ̀ torí pé ayọ̀ kún inú ọkàn” wọn.​—Àìsá. 65:​13, 14. w19.09 17 ¶15; 19 ¶21

Saturday, January 16

Mo rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn . . . wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.​—Ìfi. 7:9.

Lọ́dún 1935, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní òye tó túbọ̀ ṣe kedere nípa ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó wà nínú ìran tí Jòhánù rí. A rí i pé kò dìgbà tí ogunlọ́gọ̀ náà bá wà lọ́run kí wọ́n tó lè “dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ilẹ̀ ayé ni wọ́n wà, wọ́n “dúró níwájú ìtẹ́” náà ní ti pé wọ́n gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ, wọ́n sì fara wọn sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀. (Àìsá. 66:1) Bákan náà, wọ́n dúró “níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” ní ti pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú ìràpadà Jésù. Àpẹẹrẹ míì lohun tó wà nínú Mátíù 25:​31, 32 tó sọ pé, “a máa kó gbogbo orílẹ̀-èdè” títí kan àwọn ẹni burúkú “jọ síwájú” ìtẹ́ Jésù. Ó ṣe kedere pé ayé yìí làwọn orílẹ̀-èdè wà kì í ṣe ọ̀run. Torí náà, àtúnṣe tá a ṣe sí èrò tá a ní tẹ́lẹ̀ bọ́gbọ́n mu. Ó jẹ́ ká rí ìdí tí Bíbélì ò fi sọ pé ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà máa lọ sọ́run. Àwùjọ kan ṣoṣo ni Bíbélì sọ pé ó máa lọ sọ́run, ìyẹn sì ni àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó máa wà pẹ̀lú Jésù láti “ṣàkóso bí ọba lé ayé lórí.”​—Ìfi. 5:10. w19.09 28 ¶9

Sunday, January 17

Ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ adúróṣinṣin sí i!​—Sm. 31:23.

Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú Bábílónì Ńlá. Àmọ́, èyí kọjá kéèyàn kàn sọ pé òun ò ṣe ẹ̀sìn èké mọ́. A gbọ́dọ̀ pinnu pé ìjọsìn Jèhófà làá máa ṣe kódà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, ìlànà òdodo Jèhófà ni kó o máa tẹ̀ lé. A ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ìwàkiwà tàbí àwọn àṣàkaṣà tó kúnnú ayé yìí. Bí àpẹẹrẹ, a kì í fàyè gba ìṣekúṣe èyíkéyìí títí kan kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin tàbí kí obìnrin máa fẹ́ obìnrin. (Mát. 19:​4, 5; Róòmù 1:​26, 27) Ìkejì, a gbọ́dọ̀ máa pé jọ pẹ̀lú àwọn ará wa láti jọ́sìn Jèhófà. Ibi yòówù kó jẹ́, yálà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, láwọn ilé àdáni tàbí ní bòókẹ́lẹ́, ká ṣáà rí i pé à ń pésẹ̀ déédéé. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun mú ká ṣíwọ́ àtimáa jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará wa. Kódà ní báyìí, ó yẹ ká fọwọ́ gidi mú ìpàdé lílọ “ní pàtàkì jù lọ bí [a] ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”​—Héb. 10:​24, 25. w19.10 16 ¶6-7

Monday, January 18

[Jèhófà] jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa sin òun nìkan.​—Ẹ́kís. 34:14.

Jèhófà fẹ́ ká gbádùn ara wa, eré ìnàjú sì wà lára ohun tá a fi máa ń gbádùn ara wa. Bíbélì náà sọ pé: “Kò sóhun tó dáa fún èèyàn ju pé kó jẹ, kó mu, kó sì gbádùn iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.” (Oníw. 2:24) Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn eré ìnàjú tó wà lónìí ló lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Kì í jẹ́ káwọn èèyàn fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ìṣekúṣe wò ó, ó sì máa ń jẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra. Jèhófà nìkan la fẹ́ máa jọ́sìn, torí náà a ò lè máa “jẹun lórí tábìlì Jèhófà àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.” (1 Kọ́r. 10:​21, 22) Ẹni tá a nífẹ̀ẹ́ la máa ń bá jẹun. Lọ́nà kan náà, tá a bá yan eré ìnàjú tó ní ìwà ipá nínú, ìbẹ́mìílò, ìṣekúṣe tàbí àwọn nǹkan míì tí kò dáa, ṣe là ń jẹ oúnjẹ táwọn ọ̀tá Ọlọ́run pèsè. Ìyẹn máa ṣàkóbá fún wa, àárín àwa àti Jèhófà ò sì ní gún mọ́. w19.10 26 ¶2; 29-30 ¶11-12

Tuesday, January 19

Àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.​—2 Pét. 1:21.

Kí atẹ́gùn tó lè ṣe awakọ̀ kan láǹfààní, àwọn nǹkan méjì kan wà tó gbọ́dọ̀ ṣe. Àkọ́kọ́, ó gbọ́dọ̀ gbé ọkọ̀ ẹ̀ lọ síbi tí afẹ́fẹ́ ti ń fẹ́. Ó ṣe tán, ọkọ̀ náà ò ní kúrò lójú kan tí awakọ̀ ò bá kúrò ní èbúté níbi tó so ọkọ̀ náà sí. Ìkejì, ó gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òun ta ìgbòkun ọkọ̀ náà sókè. Síbẹ̀, ó dìgbà tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ lu aṣọ tó ta sókè ọkọ̀ náà kó tó kúrò níbi tó wà. Lọ́nà kan náà, ẹ̀mí mímọ́ nìkan ló lè mú ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́ tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa ṣiṣẹ́ dáadáa láyé wa, àwọn nǹkan méjì kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ wà níbi tí ẹ̀mí mímọ́ ti lè darí wa, ìyẹn ni pé ká máa ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́ káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ máa ṣe. Ìkejì, a gbọ́dọ̀ “ta ìgbòkun ọkọ̀” wa bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, lédè míì, ká máa ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé bá a ti ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Sm. 119:32) Ẹ̀mí mímọ́ á máa darí wa nínú ayé tó kún fún wàhálà àti àdánwò yìí, á sì mú ká jẹ́ olóòótọ́. w19.11 9 ¶8; 10 ¶11

Wednesday, January 20

Mo fún yín ní àlàáfíà mi.​—Jòh. 14:27.

Jésù ní ìdààmú ọkàn lọ́jọ́ tó lò kẹ́yìn láyé. Ó mọ̀ pé àwọn èèyànkéèyàn máa tó pa òun ní ìpa ìkà. Àmọ́ ìyẹn gangan kọ́ ló ń kó ìdààmú ọkàn bá a. Ó nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ gan-an, ó sì fẹ́ ṣe ohun táá múnú rẹ̀ dùn. Jésù mọ̀ pé tóun bá jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, òun á dá orúkọ Jèhófà láre. Yàtọ̀ síyẹn, ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn, ó sì mọ̀ pé tá a bá máa ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú, àfi kóun jẹ́ olóòótọ́ títí dópin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdààmú bá Jésù gan-an, síbẹ̀ ó ní àlàáfíà ọkàn. Ó hàn gbangba pé Jésù ní “àlàáfíà Ọlọ́run,” ìyẹn ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní torí pé ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Àlàáfíà Ọlọ́run yìí ló mú kí ọkàn Jésù balẹ̀. (Fílí. 4:​6, 7) Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó lè nírú àwọn ìṣòro tí Jésù ní, àmọ́ gbogbo wa la máa kojú àdánwò. (Mát. 16:​24, 25; Jòh. 15:20) Bíi ti Jésù, àwọn ìgbà kan máa wà tá a máa ní ìdààmú ọkàn. w19.04 8 ¶1-3

Thursday, January 21

Ẹ má ṣe pa iná ẹ̀mí.​—1 Tẹs. 5:19.

Ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé mo mọyì àǹfààní tí mo ní pé mo wà nínú apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà?’ Jèhófà ti fún wa ní ẹ̀rí tó ṣe kedere pé òun lòun ń darí ètò yìí lónìí. Ìdí ọpẹ́ wa pọ̀, mélòó la tiẹ̀ fẹ́ kà nínú ohun tí Jèhófà ṣe? (1 Tẹs. 5:18) Kí la lè ṣe táá fi hàn pé à ń ti ètò tí Jèhófà ń lò lẹ́yìn? Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wá látinú Ìwé Mímọ́ tí ètò rẹ̀ ń fún wa nínú àwọn ìtẹ̀jáde, láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè. A tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. (1 Kọ́r. 15:58) Ẹ jẹ́ ká máa wá ojúure Jèhófà kó bàa lè tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìyìn wa. Ẹ jẹ́ ká máa sin Jèhófà nìṣó torí pé a mọrírì àwọn nǹkan tó ń ṣe fún wa. Ẹ jẹ́ ká máa fún Jèhófà lóhun tó dára jù torí ìfẹ́ àtọkànwá tá a ní fún un. Bákan náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ti ètò yìí lẹ́yìn, torí pé kò sí ètò míì tí Jèhófà ń darí lónìí. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ṣe là ń fi hàn pé a mọyì àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tá a ní pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà! w19.11 25 ¶17-18

Friday, January 22

Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi . . . máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ.​—Jòh. 14:12.

Jésù ò sọ pé a máa ṣe iṣẹ́ ìyanu bíi tòun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé a máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù, a sì máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó gbòòrò ju tòun lọ. Yàtọ̀ síyẹn, a máa wàásù láwọn ibi tí òun fúnra rẹ̀ kò dé, a máa wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn, a sì máa pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà ju òun lọ. Àwọn ìbéèrè kan wà tó yẹ ká bi ara wa, yálà à ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ẹnì kan tàbí iṣẹ́ ara wa là ń ṣe. Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sí ẹni tí kì í fiṣẹ́ ṣeré? Ṣé mo máa ń tètè parí iṣẹ́ tó wà lọ́wọ́ mi, ṣé bẹ́ẹ̀ ni mi máa ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ṣé mo sì máa ń ṣe gbogbo ohun tágbára mi gbé?’ Tí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yìí, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn tàbí ọ̀gá rẹ fọkàn tán ẹ. Yàtọ̀ síyẹn, á mú kó yá àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lára láti gbọ́rọ̀ rẹ tó o bá ń wàásù fún wọn. Tó bá dọ̀rọ̀ ìwàásù àti kíkọ́ni, bi ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sẹ́ni tí kì í fiṣẹ́ ìwàásù ṣeré? Ṣé mo máa ń múra ohun tí màá bá àwọn èèyàn sọ sílẹ̀ dáadáa? Ṣé mo máa ń mú àdéhùn mi ṣẹ tí mo bá ṣèlérí pé màá pa dà wá? Ṣé gbogbo apá tí iṣẹ́ ìwàásù wa pín sí ni mo máa ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀ déédéé?’ Tí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yìí, ó dájú pé wàá máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ náà. w19.12 5 ¶14-15

Saturday, January 23

Kí kálukú yín nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; bákan náà, kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.​—Éfé. 5:33.

Ìbéèrè pàtàkì méjì kan wà tó yẹ káwọn tọkọtaya wá ìdáhùn sí tí wọ́n bá pinnu pé àwọn máa bímọ: Àkọ́kọ́, ìgbà wo ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ? Ìkejì, ọmọ mélòó ni wọ́n máa bí? Àmọ́, ìgbà wo ló bọ́gbọ́n mu pé kí tọkọtaya jọ sọ̀rọ̀ yìí? Kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n jọ fẹnu kò lórí ọ̀rọ̀ yìí? Lọ́pọ̀ ìgbà, àsìkò tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà ló bọ́gbọ́n mu jù pé kí wọ́n jọ pinnu bóyá àwọn máa bímọ tàbí àwọn ò ní bímọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí kan ni pé á jẹ́ kí wọ́n lè gbọ́ ara wọn yé kí wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan. Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá agbára àwọn á lè gbé ẹrù ọmọ títọ́ tàbí kò ní lè gbé e. Àwọn tọkọtaya kan pinnu pé àwọn á mú sùúrù fún ọdún kan tàbí méjì káwọn tó bímọ torí pé ọmọ títọ́ máa ń tánni lókun, ó sì ń gba ọ̀pọ̀ àkókò. Wọ́n gbà pé táwọn bá mú sùúrù díẹ̀, á jẹ́ káwọn túbọ̀ sún mọ́ra, káwọn sì túbọ̀ mọwọ́ ara àwọn. w19.12 23 ¶4-5

Sunday, January 24

Ọ̀rẹ́ tòótọ́ . . . jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.​—Òwe 17:17.

Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń kojú onírúurú ìṣòro, bóyá ni ibì kan wà láyé yìí tí nǹkan ti dẹrùn, àwọn ìṣòro ọ̀hún ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni, wọ́n sì ń tánni lókun. Àìsàn tó lágbára tàbí àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ ló ń bá àwọn kan fínra, nígbà táwọn míì ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn wọn tó kú. Ohun tó ń ba àwọn míì nínú jẹ́ ni ti èèyàn wọn tí kò sin Jèhófà mọ́. Ní tàwọn míì, àjálù tó ṣẹlẹ̀ àti ràbọ̀ràbọ̀ ẹ̀ ló ń fa ẹ̀dùn ọkàn fún wọn. Ó ṣe kedere pé àwọn ará wa yìí nílò ìtùnú, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ìbéèrè náà ni pé, kí la lè ṣe láti tù wọ́n nínú? Jẹ́ ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini. Àwọn ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini nígbà ìṣòro máa ń fi ara wọn jìn nítorí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí wọ́n ṣàyẹ̀wò fún arákùnrin kan tó ń jẹ́ Peter, dókítà sọ fún un pé ó ní àìsàn burúkú kan tó máa tó gbẹ̀mí ẹ̀. Kathryn ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Tọkọtaya kan tá a jọ wà nínú ìjọ ló gbé wa lọ sílé ìwòsàn tí wọ́n ti ṣe àyẹ̀wò fún ọkọ mi. Wọ́n pinnu pé àwọn ò ní dá wa dá ìṣòro náà, pé àwọn á dúró tì wá, ohun tí wọ́n sì ṣe gan-an nìyẹn torí pé wọn ò fi wá sílẹ̀ rárá.” Ẹ wo bó ṣe máa tuni lára tó téèyàn bá ní àwọn ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini nígbà ìṣòro! w20.01 8 ¶1; 9 ¶5; 10 ¶6

Monday, January 25

Gbogbo wọn . . . kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ oríṣiríṣi èdè.​—Ìṣe 2:4.

Ká sọ pé o wà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó wà nínú yàrá òkè lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó dájú pé o ò ní ṣiyèméjì pé Jèhófà ti fi ẹ̀mí mímọ́ yàn ẹ́. (Ìṣe 2:​5-12) Àmọ́ ṣé gbogbo àwọn ẹni àmì òróró ni ẹ̀mí mímọ́ bà lé lọ́nà ìyanu, ṣé gbàrà tí wọ́n ṣèrìbọmi tàbí ṣáájú ìrìbọmi ni gbogbo wọn rí ẹ̀mí mímọ́ gbà? Rárá ni ìdáhùn. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àsìkò tí Jèhófà fi ẹ̀mí yàn wọ́n. Kì í ṣe àwọn bí ọgọ́fà (120) yẹn nìkan ni Jèhófà fẹ̀mí yàn lọ́jọ́ yẹn. Lọ́jọ́ yẹn kan náà, Jèhófà tún fẹ̀mí yan àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) míì. Ìgbà tí wọ́n ṣèrìbọmi ni Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. (Ìṣe 2:​37, 38, 41) Àmọ́ bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, nǹkan yàtọ̀ torí pé kì í ṣe ìgbà ìrìbọmi ni Jèhófà fẹ̀mí yan gbogbo Kristẹni tó jẹ́ ẹni àmì òróró. Bí àpẹẹrẹ, ó ti ṣe díẹ̀ lẹ́yìn táwọn ará Samáríà kan ṣèrìbọmi kí wọ́n tó rí ẹ̀mí mímọ́ gbà. (Ìṣe 8:​14-17) Ti Kọ̀nílíù àtàwọn ará ilé rẹ̀ tiẹ̀ yàtọ̀ pátápátá torí pé kí wọ́n tó ṣèrìbọmi rárá ni Jèhófà ti fẹ̀mí yàn wọ́n.​—Ìṣe 10:​44-48. w20.01 20-21 ¶2-4

Tuesday, January 26

Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ.​—Jòh. 17:26.

Nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nìkan, ó lé ní ọgọ́rùn-ún ìgbà tí Jésù pe Jèhófà ní “Baba.” Kí nìdí? Ìdí kan ni pé ó fẹ́ kó dá àwa èèyàn lójú pé Baba tó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an ni Jèhófà. (Jòh. 17:25) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ nípa Jèhófà nínú bó ṣe bá Jésù Ọmọ rẹ̀ lò. Ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń tẹ́tí sí àdúrà Jésù. Kì í ṣe pé ó ń tẹ́tí sí i nìkan, ó tún máa ń dáhùn àdúrà rẹ̀. (Jòh. 11:​41, 42) Bákan náà, kò sígbà tí Jésù kojú àdánwò tí kì í rọ́wọ́ Jèhófà, ó sì máa ń rí i pé Baba òun nífẹ̀ẹ́ òun. (Lúùkù 22:​42, 43) Torí pé Baba tó nífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó mú kó dá Jésù lójú pé òun wà lẹ́yìn rẹ̀. (Mát. 26:53; Jòh. 8:16) Òótọ́ ni pé Jèhófà fàyè gba pé kí wọ́n fìyà jẹ Jésù, síbẹ̀ ó ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á. Jésù mọ̀ pé ìṣòro yòówù kó dé bá òun, fúngbà díẹ̀ ni. (Héb. 12:2) Jèhófà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jésù ní ti pé ó tẹ́tí sí i, ó pèsè ohun tó nílò, ó dá a lẹ́kọ̀ọ́, ó sì tì í lẹ́yìn.​—Jòh. 5:20; 8:28. w20.02 3 ¶6-7, 9

Wednesday, January 27

Ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run. Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹ má bàa di ohun ìkọ̀sẹ̀.​—1 Kọ́r. 10:​31, 32.

Nígbà tá a bá ń pinnu bóyá ká lọ́wọ́ nínú àṣà kan tàbí ká má ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká tún ronú nípa bí ìpinnu wa ṣe máa rí lára àwọn Kristẹni bíi tiwa àtàwọn míì. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀. (Máàkù 9:42) Bákan náà, a ò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa bí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, àá fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bá wọn sọ̀rọ̀, ìyẹn sì máa fògo fún Jèhófà. Kò ní bójú mu ká máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí ká máa bẹnu àtẹ́ lu àṣà wọn. Ká rántí pé ìfẹ́ lágbára gan-an. Tá a bá fìfẹ́ hàn sáwọn tó ń fúngun mọ́ wa, tá a sì bọ̀wọ̀ fún wọn, ó ṣeé ṣe kí ọkàn wọn rọ̀. Jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́. (Àìsá. 43:10) Tó o bá ti jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn aládùúgbò rẹ mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, á rọrùn fún ẹ láti kọ̀ tí wọ́n bá ní kó o lọ́wọ́ nínú àṣà tí kò bá Bíbélì mu. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní tijú àtisọ ohun tá a gbà gbọ́ nípa ipò táwọn òkú wà, àá sì dúró lórí ìgbàgbọ́ wa.​—Róòmù 1:16. w19.04 17-18 ¶14-16

Thursday, January 28

Èmi ló kéré jù nínú àwọn àpọ́sítélì, mi ò sì yẹ lẹ́ni tí à ń pè ní àpọ́sítélì.​—1 Kọ́r. 15:9.

Àwọn àpọ́sítélì méjìlá yẹn ló wà pẹ̀lú Jésù nígbà tó ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àmọ́ ẹ̀yìn ikú àti àjíǹde Jésù ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù di Kristẹni. Òótọ́ ni pé Jésù yan Pọ́ọ̀lù láti jẹ́ “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè,” síbẹ̀ kò di ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá náà. (Róòmù 11:13; Ìṣe 1:​21-26) Kàkà kó jowú pé òun ò jẹ, òun ò sì mu pẹ̀lú Jésù bíi tàwọn àpọ́sítélì méjìlá yẹn, ó mọyì àǹfààní tó ní, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn. Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tá a sì ní ìtẹ́lọ́rùn, a máa ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù, àá sì máa bọ̀wọ̀ fáwọn tí Jèhófà yàn sípò. (Ìṣe 21:​20-26) Jèhófà ló ṣètò pé kí àwọn alàgbà máa múpò iwájú nínú ìjọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wọ́n, Jèhófà kà wọ́n sí “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn.” (Éfé. 4:​8, 11) Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fún àwọn tí Jèhófà yàn sípò tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń fún wa, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà á túbọ̀ gún régé, àlàáfíà á sì jọba nínú ìjọ. w20.02 17 ¶13-14

Friday, January 29

A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.​—1 Jòh. 4:19.

Káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́, ó ṣeé ṣe kó o fẹ́ràn àtimáa ka Bíbélì. Ó sì ṣeé ṣe kó o nífẹ̀ẹ́ Jésù náà. Ní báyìí tá a ti ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́, ó ṣeé ṣe kó o ti máa dara pọ̀ mọ́ wa. Ó dájú pé o mọyì àwọn nǹkan rere tó ò ń gbádùn. Ó dáa bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ tó o sì ń wá sípàdé, àmọ́ àwọn nǹkan yìí ò tó láti mú kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó o sì ṣèrìbọmi. Ohun tó ṣe pàtàkì jù táá mú kó o ṣèrìbọmi ni ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà Ọlọ́run. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ju ohunkóhun míì lọ, o ò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti jọ́sìn ẹ̀. Torí náà, ìfẹ́ fún Jèhófà lá mú kó o ṣèrìbọmi, òun náà lá sì mú kó o fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi. Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ fi gbogbo ọkàn wa, gbogbo ara wa, gbogbo èrò wa àti gbogbo okun wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Máàkù 12:30) Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kó o sì máa bọ̀wọ̀ fún un? Á dáa kó o ronú jinlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, ìyẹn á sì mú kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. w20.03 4 ¶4-5

Saturday, January 30

Ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láìkù síbì kan.​—2 Tím. 4:5.

Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láìkù síbì kan? Tá a bá sọ pé ẹnì kan ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láìkù síbì kan, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. Àmọ́, ó kọjá kéèyàn lo ọ̀pọ̀ wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ìdí ni pé kì í ṣe bí àkókò tá a lò ṣe pọ̀ tó ni Jèhófà ń wò, bí kò ṣe ìdí tá a fi ń ṣe é. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa ló ń mú ká máa lo ara wa tọkàntọkàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (Máàkù 12:​30, 31; Kól. 3:23) Ẹni tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn kì í fọwọ́ hẹ iṣẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa ń fi gbogbo okun àti agbára rẹ̀ ṣe iṣẹ́ Jèhófà. Tá a bá mọyì àǹfààní tá a ní láti wàásù, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí ọ̀pọ̀ èèyàn lè gbọ́ ìhìn rere bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Iṣẹ́ tá à ń ṣe lè mú kó ṣòro fún wa láti lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bó ti wù kó rí, iṣẹ́ ìwàásù la fẹ́ràn jù. Fún ìdí yìí, a máa ń sapá ká lè sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kí ọ̀rọ̀ wa sì lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wa máa ń dí, iṣẹ́ ìwàásù ló gbà wá lọ́kàn jù. w19.04 2 ¶3; 3 ¶4, 6

Sunday, January 31

Òtítọ́ ò sí nínú rẹ̀.​—Jòh. 8:44.

Irọ́ Sátánì ń pa kún ìṣòro àti ẹ̀dùn ọkàn táwọn èèyàn ní. Wọ́n lè sọ fún àwọn òbí tí ọmọ wọn kú pé Ọlọ́run tó fún wọn lọ́mọ náà ló gbà á, àti pé ọmọ náà wà lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ṣé irọ́ yìí máa ń tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú àbí ṣe ló tún ń dá kún un? Ẹ̀kọ́ nípa iná ọ̀run àpáàdì wà lára ohun táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ìgbà yẹn fi kẹ́wọ́ láti máa dá àwọn èèyàn lóró, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń finá sun àwọn tó bá ta ko ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Ìwé kan sọ ohun tó ṣeé ṣe kó fà á táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yẹn fi ń dáná sun àwọn tó ta ko ẹ̀kọ́ wọn. Wọ́n gbà pé báwọn ṣe ń finá sun wọ́n yẹn máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé iná ọ̀run àpáàdì kọjá kèrémí, nípa bẹ́ẹ̀ ó ṣeé ṣe káwọn alátakò ṣọ́ọ̀ṣì yẹn ronú pìwà dà kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ iná ọ̀run àpáàdì. Láwọn ilẹ̀ kan, ìbẹ̀rù òkú ti mú kí wọ́n máa júbà àwọn tí wọ́n pè ní alálẹ̀ tàbí àwọn baba ńlá wọn, wọ́n sì máa ń rúbọ tàbí gbàdúrà sí wọn kí wọ́n lè rí ìbùkún gbà. Àwọn míì máa ń wá ojúure òkú kó má bàa fìyà jẹ wọ́n. Ó ṣeni láàánú pé kàkà kí àwọn ẹ̀kọ́ èké Sátánì yẹn mú ìtura bá àwọn èèyàn, ìnira, àníyàn àti ìpayà ló ń kó bá wọn. w19.04 14 ¶1; 16 ¶10

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́