February
Monday, February 1
[Jèhófà] nífẹ̀ẹ́ . . . ìdájọ́ òdodo.—Sm. 33:5.
Nínú Bíbélì, “ìdájọ́ òdodo” túmọ̀ sí pé kéèyàn ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run láìṣe ojúsàájú. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tí Jésù ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo. Nígbà ayé Jésù, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù kórìíra àwọn tí kì í ṣe Júù, wọ́n ka àwọn Júù tí kò lọ sílé ìwé àwọn rábì sí gbáàtúù, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò ka àwọn obìnrin sí. Àmọ́ Jésù ní tiẹ̀ kò ṣojúsàájú, ó sì ṣojúure sí gbogbo èèyàn. Ó jẹ́ káwọn tó nígbàgbọ́ tẹ̀ lé òun, yálà wọ́n jẹ́ Júù tàbí wọn kì í ṣe Júù. (Mát. 8:5-10, 13) Gbogbo èèyàn ló wàásù fún, àtolówó àti tálákà. (Mát. 11:5; Lúùkù 19:2, 9) Kò tẹ́ńbẹ́lú àwọn obìnrin, bẹ́ẹ̀ sì ni kò hùwà ìkà sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ọ̀wọ̀ wọ àwọn obìnrin, títí kan àwọn táwọn míì kà sí aláìjámọ́ nǹkan kan. (Lúùkù 7:37-39, 44-50) A lè fara wé Jésù tá a bá ń hùwà tó dáa sáwọn èèyàn láìṣe ojúsàájú, tá a sì ń wàásù fún gbogbo èèyàn láìka ipò wọn láwùjọ tàbí ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí. Àwọn arákùnrin ń fara wé Jésù bí wọ́n ṣe ń fi ọ̀wọ̀ wọ àwọn obìnrin. w19.05 2 ¶1; 5 ¶15-17
Tuesday, February 2
A di ẹni jẹ́jẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.—1 Tẹs. 2:7.
Ó yẹ káwọn alàgbà máa lo ọ̀rọ̀ tútù tó ń mára tuni bí wọ́n ṣe ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tu àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú. Ṣé àwọn alàgbà nìkan ló lè pèsè ìtùnú fáwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé? Rárá o. Ìdí ni pé ojúṣe gbogbo wa ni láti máa ‘tu ara wa nínú.’ (1 Tẹs. 4:18) Ó ṣàǹfààní gan-an táwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn bá lè tu àwọn arábìnrin míì nínú. Ó ṣe tán, Jèhófà fi ara rẹ̀ wé abiyamọ tó ń tu ọmọ rẹ̀ nínú. (Àìsá. 66:13) Bíbélì tiẹ̀ mẹ́nu kan àwọn obìnrin tó tu àwọn míì tó ní ìdààmú ọkàn nínú. (Jóòbù 42:11) Kò sí àní-àní pé inú Jèhófà ń dùn bó ṣe ń rí àwọn arábìnrin tó ń pèsè ìtùnú fáwọn arábìnrin míì tó ní ìdààmú ọkàn! Nígbà míì, alàgbà kan tàbí méjì lè fọgbọ́n sọ fún arábìnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ pé kó sún mọ́ arábìnrin kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn, kó sì tù ú nínú. Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká ṣọ́ra ká má lọ tojú bọ ọ̀rọ̀ tí Kristẹni kan ò ní fẹ́ káwọn míì mọ̀.—1 Tẹs. 4:11. w19.05 16-17 ¶10-12
Wednesday, February 3
Nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta, a ó fìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀.—Mát. 18:16.
Nínú ìjọ, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹni méjì, ó kéré tán gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ kan káwọn alàgbà tó lè yan ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́? Ìdí ni pé ìlànà yìí wà lára ohun tí Bíbélì sọ pé a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé tó bá kan ọ̀rọ̀ ìdájọ́. Tẹ́ni tó hùwà burúkú kò bá jẹ́wọ́ ohun tó ṣe, ẹni méjì gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan onítọ̀hún, ìgbà yẹn làwọn alàgbà tó lè yan ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà. (Diu. 19:15; 1 Tím. 5:19) Tẹ́ni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn bá sẹ́ pé òun ò ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà á ní káwọn ẹlẹ́rìí sọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà. Tẹ́ni méjì bá jẹ́rìí sí i, tí wọ́n sì fìdí ẹ̀sùn náà múlẹ̀, àwọn alàgbà á yan ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́. Ká tiẹ̀ sọ pé kò ṣeé ṣe láti fìdí ẹ̀sùn náà múlẹ̀ torí pé ẹlẹ́rìí ò pé méjì, àwọn alàgbà ṣì máa gbà pé ó ṣeé ṣe kẹ́ni náà hùwà ọ̀hún lóòótọ́. Fún ìdí yìí, àwọn alàgbà á máa pèsè ìtùnú látìgbàdégbà fáwọn tó ṣeé ṣe kọ́rọ̀ náà kó ẹ̀dùn ọkàn bá. Bákan náà, àwọn alàgbà máa wà lójúfò kí wọ́n bàa lè dáàbò bo àwọn ará ìjọ.—Ìṣe 20:28. w19.05 11 ¶15-16
Thursday, February 4
Máa ronú lórí àwọn nǹkan yìí . . . , kí gbogbo èèyàn lè rí i kedere pé ò ń tẹ̀ síwájú.—1 Tím. 4:15.
Ẹ gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n ṣe lè máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n gbọ́dọ̀ mọ bí wọ́n á ṣe máa múra ìpàdé sílẹ̀ àti béèyàn ṣe ń ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan tí wọ́n ń kojú nílé ìwé. (Héb. 5:14) Tí wọ́n bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ nílé, á rọrùn fún wọn láti pọkàn pọ̀ nípàdé àti láwọn àpéjọ. Àmọ́, ẹ má gbàgbé pé ọjọ́ orí àwọn ọmọ yín àti bí wọ́n ṣe ń fara balẹ̀ tó ló máa pinnu iye àkókò tẹ́ ẹ máa lò. Ó ṣe pàtàkì káwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa náà mọ bí wọ́n ṣe lè dá kẹ́kọ̀ọ́. Níbẹ̀rẹ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa fàlà sí ìdáhùn tí wọ́n bá ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn tàbí ìpàdé sílẹ̀, èyí sì máa ń múnú wa dùn. Àmọ́, ó yẹ ká kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa ṣèwádìí àti bí wọ́n ṣe lè ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó nítumọ̀. Tí wọ́n bá kojú ìṣòro, wọ́n á mọ bí wọ́n ṣe lè ṣèwádìí nípa ìṣòro náà dípò kí wọ́n máa wá àwọn ará táá bá wọn wá ojútùú sí i. w19.05 26 ¶2; 28 ¶10-11
Friday, February 5
À ń borí àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga tí kò bá ìmọ̀ Ọlọ́run mu.—2 Kọ́r. 10:5.
Gbogbo ọ̀nà ni Sátánì ń wá láti yí wa lérò pa dà. Onírúurú èrò òdì ló sì ń lò ká má bàa fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìbéèrè kan náà tí Sátánì bi Éfà lọ́jọ́sí náà ló ṣì ń dọ́gbọ́n bi àwa náà, ó béèrè lọ́wọ́ Éfà pé: “Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé . . . ?” (Jẹ́n. 3:1) Nínú ayé èṣù yìí, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn máa ń béèrè àwọn ìbéèrè tó lè mú ká ṣiyèméjì, bíi: ‘Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé kò dáa kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin tàbí kí obìnrin máa fẹ́ obìnrin? Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àti Kérésìmesì? Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run yín sọ pé kẹ́ ẹ má ṣe gba ẹ̀jẹ̀ tẹ́ ẹ bá ń ṣàìsàn? Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run ìfẹ́ máa sọ pé kẹ́ ẹ má ṣe kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn yín torí pé wọ́n yọ wọ́n lẹ́gbẹ́?’ Ó yẹ kí ohun tá a gbà gbọ́ dá wa lójú. Ìdí sì ni pé tá ò bá wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó lè mú ká ṣiyèméjì, kò ní pẹ́ tá a fi máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì. Tá ò bá ṣọ́ra, èrò òdì lè gbilẹ̀ lọ́kàn wa, kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa sì rì. w19.06 12-13 ¶15-17
Saturday, February 6
Kí èrò gbogbo yín ṣọ̀kan, kí ẹ máa bára yín kẹ́dùn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ ará, kí ẹ lójú àánú, kí ẹ sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.—1 Pét. 3:8.
Jèhófà Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Jòh. 3:16) Ó sì yẹ káwa náà fara wé e. Torí náà, gbogbo èèyàn ló yẹ ká máa bá kẹ́dùn, ká nífẹ̀ẹ́ wọn, ká sì máa fàánú hàn sí wọn. Àmọ́ ní pàtàkì, ó yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ sáwọn “tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gál. 6:10) Nígbà táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa bá ní ìdààmú ọkàn, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Báwo la ṣe lè tu ẹni tó pàdánù ọkọ tàbí aya rẹ̀ nínú? Ohun àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì ká ṣe ni pé ká bá ẹni náà sọ̀rọ̀ kódà tó bá ń ṣe wá bákan tàbí tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò mọ ohun tá a lè sọ. Paula tí ọkọ rẹ̀ ṣàdédé kú sọ pé: “Mo mọ̀ pé kì í rọrùn fáwọn èèyàn tí wọ́n bá gbọ́ pé èèyàn ẹnì kan kú. Wọ́n lè máa bẹ̀rù pé àwọn lè ṣi ọ̀rọ̀ sọ lọ́dọ̀ ẹni náà. Àmọ́ ní tèmi, ó sàn tí ẹnì kan bá sọ ọ̀rọ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ bọ́ sójú ẹ̀ ju pé kó kàn dákẹ́ láìsọ nǹkan kan.” Òótọ́ kan ni pé ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ ò retí pé ká sọ ohun tó máa yanjú ìṣòro òun. Paula wá fi kún un pé: “Ó máa ń tù mí lára táwọn ọ̀rẹ́ mi bá kàn sọ fún mi pé, ‘Ikú ọkọ yín dùn wá gan-an.’ ” w19.06 20 ¶1; 23 ¶14
Sunday, February 7
Jèhófà, fiyè sí ìhàlẹ̀ wọn, kí o sì jẹ́ kí àwa ẹrú rẹ máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ nìṣó pẹ̀lú ìgboyà.—Ìṣe 4:29.
Tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa, àwọn alàgbà máa ṣètò bí àá ṣe máa ṣèpàdé láìjẹ́ káwọn èèyàn fura sí wa. Wọ́n lè ṣètò yín sí àwùjọ kéréje láti máa ṣèpàdé, wọ́n sì lè yí ibi tẹ́ ẹ ti ń ṣèpàdé àti àsìkò tẹ́ ẹ̀ ń ṣe é pa dà látìgbàdégbà. Tó bá dọ̀rọ̀ ìwàásù, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé ọ̀nà tá a máa gbà wàásù níbì kan lè yàtọ̀ sí ti ibòmíì. Àmọ́ torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì gbádùn ká máa sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn, àá wá bá a ṣe máa wàásù fún wọn. (Lúùkù 8:1) Nígbà tí òpìtàn kan tó ń jẹ́ Emily B. Baran ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará wa lábẹ́ ìjọba Soviet Union àtijọ́, ó sọ pé: “Nígbà tí ìjọba ṣòfin pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gbọ́dọ̀ wàásù fáwọn míì, ńṣe ni wọ́n ń dọ́gbọ́n bá àwọn aládùúgbò wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn àtàwọn ará ibiṣẹ́ wọn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tọ́wọ́ àwọn aláṣẹ bá tẹ̀ wọ́n, tí wọ́n sì jù wọ́n sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí tún máa ń wàásù fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n bá níbẹ̀.” Àbẹ́ ò rí nǹkan, láìka ìfòfindè sí, àwọn ará yẹn ò dẹ́kun wíwàásù fáwọn èèyàn. Torí náà, rántí àpẹẹrẹ àwọn ará yẹn, kó o sì fara wé wọn. w19.07 11 ¶12-13
Monday, February 8
Ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 28:19.
Báwo la ṣe lè mú kí àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi? Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ibi tẹ́nì kan gbé dàgbà máa ń nípa lórí bóyá á tẹ́tí sí ìwàásù wa tàbí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìṣarasíhùwà àwọn ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù sí ìwàásù wa lè yàtọ̀ sí tẹni tó wá láti ilẹ̀ Éṣíà. Kí nìdí? Nílẹ̀ Yúróòpù, ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ nípa Bíbélì tí wọ́n sì ti kọ́ wọn pé Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá àwọn nǹkan. Àmọ́ láwọn orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà, èyí tó pọ̀ jù níbẹ̀ ni kò mọ ohunkóhun nípa Bíbélì, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà. Torí náà, gbà pé wọ́n lè yí pa dà. Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn tẹ́lẹ̀ ló ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àtilẹ̀ lọ̀pọ̀ wọn ti kórìíra ìwàkiwà àti àgàbàgebè tó kúnnú ẹ̀sìn. Onírúurú ìwàkiwà làwọn míì ń hù tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti ń wá bí wọ́n ṣe máa jáwọ́ nínú wọn. Torí náà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó dájú pé a máa rí “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun.”—Ìṣe 13:48; 1 Tím. 2:3, 4. w19.07 20-21 ¶3-4
Tuesday, February 9
A kò juwọ́ sílẹ̀.—2 Kọ́r. 4:16.
Yálà ọ̀run là ń lọ tàbí ayé yìí la máa wà, ẹ jẹ́ ká sapá kọ́wọ́ wa lè tẹ èrè náà. Ìṣòro yòówù kó máa bá wa fínra, ẹ má ṣe jẹ́ ká wo àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn, ká má sì jẹ́ kí ohunkóhun mú ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (Fílí. 3:16) Àwọn ohun tá à ń retí lè má dé lásìkò tá a fẹ́, ara tó ń dara àgbà sì lè mú kí nǹkan nira fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, a lè ti fara da ọ̀pọ̀ àdánwò àti inúnibíni látọdún yìí wá. Èyí ó wù kó jẹ́, “ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á fún wa ní àlàáfíà tó kọjá gbogbo òye wa. (Fílí. 4:6, 7) Bíi ti sárésáré kan tó ń sa gbogbo ipá rẹ̀ bó ṣe ń sún mọ́ ìparí, ẹ jẹ́ káwa náà sa gbogbo ipá wa, ká sì gbájú mọ́ ìrètí ọjọ́ iwájú bá a ti ń sún mọ́ òpin eré ìje ìyè náà. Láìka bí ipò wa ṣe rí, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. w19.08 7 ¶16-17
Wednesday, February 10
Ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.—Róòmù 12:15.
A lè má mọ ohun tá a máa sọ fún ẹnì kan tó ń ṣọ̀fọ̀. Àmọ́ ká rántí pé omijé wa sọ púpọ̀ ju ọ̀rọ̀ ẹnu lọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Lásárù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù kú, Màríà, Màtá àtàwọn míì sunkún nítorí pé èèyàn wọn lẹni tó kú náà. Nígbà tí Jésù débẹ̀ lọ́jọ́ kẹrin, òun náà “da omi lójú,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé òun máa jí Lásárù dìde. (Jòh. 11:17, 33-35) Bí Jésù ṣe sunkún jẹ́ ká mọ bí ikú Lásárù ṣe máa rí lára Jèhófà. Ó tún fi hàn pé Jésù nífẹ̀ẹ́ ìdílé tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà. Kò sí àní-àní pé ohun tí Jésù ṣe yẹn tu Màríà àti Màtá nínú. Lọ́nà kan náà, tá a bá fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀, tá a sì fi ìmọ̀lára tòótọ́ hàn, wọ́n á gbà pé a nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ ló yí àwọn ká. Nígbà míì, ohun tó dáa jù ni pé ká tẹ́tí sí ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ náà dáadáa. Ó ṣe pàtàkì kó o fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, má sì jẹ́ káwọn ọ̀rọ̀ tó dà bí “ọ̀rọ̀ ẹhànnà” bí ẹ nínú. (Jóòbù 6:2, 3) Ó ṣeé ṣe káwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ máa fúngun mọ́ ọn pé kó lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu. Torí náà, ẹ jọ gbàdúrà pa pọ̀. Bẹ “Olùgbọ́ àdúrà” pé kó fún un lókun àti ọgbọ́n táá jẹ́ kó lè ṣèpinnu tó tọ́.—Sm. 65:2. w19.04 18-19 ¶18-19
Thursday, February 11
Ẹ tú ọkàn yín jáde níwájú rẹ̀.—Sm. 62:8.
Yálà Bẹ́tẹ́lì la ti ń sìn tàbí pápá, a máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn tó yí wa ká, ara wa sì máa ń mọlé níbi tá a ti ń sìn. Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé iṣẹ́ wa yí pa dà tó sì gba pé ká fibẹ̀ sílẹ̀, ọkàn wa máa ń gbọgbẹ́. A lè máa ṣàárò àwọn tá a fi sílẹ̀, a sì lè máa ṣàníyàn nípa wọn, pàápàá tó bá jẹ́ pé inúnibíni ló mú ká kúrò níbẹ̀. (Mát. 10:23; 2 Kọ́r. 11:28, 29) Yàtọ̀ síyẹn, ṣe lèèyàn máa ń dà bí àjèjì níbi tuntun tó bá lọ, kódà kó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ ló pa dà sí. Àwọn tí iṣẹ́ ìsìn wọn yí pa dà lè níṣòro ìṣúnná owó. Nǹkan lè tojú sú wọn, ọkàn wọn lè dàrú, wọ́n sì lè rẹ̀wẹ̀sì. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni wọ́n lè ṣe? Túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Jém. 4:8) Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sm. 65:2) Bíbélì fi dá wa lójú pé Jèhófà “lè ṣe ọ̀pọ̀ yanturu ju ohun tó ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a ronú kàn.” (Éfé. 3:20) Kì í ṣe àwọn nǹkan tá a dìídì béèrè nínú àdúrà wa nìkan ni Jèhófà máa ń ṣe. Ó máa ń ṣe kọjá ohun tá a retí àtohun tá a lérò láti yanjú ìṣòro wa. w19.08 21 ¶5-6
Friday, February 12
Wọ́n sì kó wọn jọ sí . . . Amágẹ́dọ́nì.—Ìfi. 16:16.
Ǹjẹ́ o ti gbọ́ ọ rí káwọn èèyàn pe “Amágẹ́dọ́nì” ní ogun runlérùnnà tàbí ìjábá ńlá kan tó máa pa ayé run? Àmọ́, ìròyìn ayọ̀ ni Bíbélì pe Amágẹ́dọ́nì, kódà ìròyìn tó ń múnú ẹni dùn ni! (Ìfi. 1:3) Ogun Amágẹ́dọ́nì kò ní pa ayé run, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa tún ayé ṣe! Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Bíbélì fi hàn pé ogun Amágẹ́dọ́nì máa fòpin sí ìṣàkóso èèyàn, á sì tipa bẹ́ẹ̀ dá aráyé nídè. Ogun yìí máa pa àwọn ẹni ibi run, á sì dá àwọn olódodo sí. Ó tún máa gba aráyé là torí pé kò ní jẹ́ kí ayé yìí pa run. (Ìfi. 11:18) Ẹ̀ẹ̀kan péré ni ọ̀rọ̀ náà “Amágẹ́dọ́nì” fara hàn nínú Ìwé Mímọ́, ó sì wá látinú ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tó túmọ̀ sí “Òkè Mẹ́gídò.” (Ìfi. 16:16; àlàyé ìsàlẹ̀) Ìlú kan ló ń jẹ́ Mẹ́gídò ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́. (Jóṣ. 17:11) Àmọ́, Amágẹ́dọ́nì kì í ṣe ibì kan pàtó lórí ilẹ̀ ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń tọ́ka sí bí “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” ṣe máa kóra jọ lòdì sí Jèhófà.—Ìfi. 16:14. w19.09 8 ¶1-3
Saturday, February 13
Kò sì tíì rí ìwòsàn lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni.—Lúùkù 8:43.
Nǹkan ò dẹrùn fún obìnrin yẹn, ẹni tó máa ràn án lọ́wọ́ ló ń wá. Bó ṣe ń kúrò lọ́dọ̀ dókítà kan ló ń lọ sọ́dọ̀ òmíì. Odindi ọdún méjìlá (12) ló fi pààrà ilé ìwòsàn, síbẹ̀ pàbó ló já sí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, nínú Òfin Mósè, aláìmọ́ ni. (Léf. 15:25) Ó gbọ́ pé Jésù ń wo àwọn aláìsàn sàn, torí náà ó wá Jésù lọ. Nígbà tó rí i, ó fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ara rẹ̀ sì yá! Kì í ṣe pé Jésù wo obìnrin náà sàn nìkan, ó tún pọ́n ọn lé lójú gbogbo èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù máa bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, èdè àpọ́nlé tó sì fìfẹ́ hàn ló fi pè é. Ó pè é ní “ọmọbìnrin.” Ẹ wo bí inú obìnrin yẹn ti máa dùn tó pé òun bọ́ lọ́wọ́ àìsàn burúkú tó ń ṣe òun! (Lúùkù 8:44-48) Ẹ kíyè sí i pé obìnrin yẹn ló tọ Jésù lọ. Òun ló sapá láti wá Jésù rí. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, a gbọ́dọ̀ sapá láti lọ “sọ́dọ̀” Jésù. Lásìkò wa yìí, Jésù ò ní wo ẹnikẹ́ni tó “wá sọ́dọ̀” ẹ̀ sàn lọ́nà ìyanu. Síbẹ̀, ó ṣì ń pè wá pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi . . . màá sì tù yín lára.”—Mát. 11:28. w19.09 20 ¶2-3
Sunday, February 14
Mo rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn . . . wọ́n wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n.—Ìfi. 7:9.
Wòlíì Sekaráyà náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fara jọ èyí, ó ní: “Ní àwọn ọjọ́ yẹn, ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò di aṣọ Júù kan mú, àní wọn yóò dì í mú ṣinṣin, wọ́n á sì sọ pé: ‘A fẹ́ bá yín lọ, torí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’ ” (Sek. 8:23) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé kí àwọn èèyàn látinú gbogbo èdè tó lè di ara ogunlọ́gọ̀ náà, a gbọ́dọ̀ máa wàásù ní ọ̀pọ̀ èdè. Lónìí, àwa là ń ṣiṣẹ́ ìtumọ̀ tó gbòòrò jù lọ láyé torí pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè là ń tú àwọn ìwé wa sí. Ó ṣe kedere pé iṣẹ́ ìyanu ńlá ni Jèhófà ń gbé ṣe lónìí bó ṣe ń kó àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè jọ. Torí pé Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde míì ti wà lónírúurú èdè, ó ti ṣeé ṣe fún ogunlọ́gọ̀ náà láti máa jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá. Kódà ibi gbogbo làwọn èèyàn ti mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fìtara wàásù, a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa gan-an. Ẹ ò rí i pé ìyẹn mórí ẹni wú!—Mát. 24:14; Jòh. 13:35. w19.09 30-31 ¶16-17
Monday, February 15
Ìpọ́njú ńlá máa wà nígbà náà, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di báyìí, àní, irú rẹ̀ kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.—Mát. 24:21.
Nígbà ìpọ́njú ńlá, ó máa ya àwọn èèyàn lẹ́nu gan-an tí wọ́n bá rí i pé gbogbo ohun tí wọ́n gbára lé bẹ̀rẹ̀ sí í dojú rú, wọ́n á sì rí i pé àwọn nǹkan yẹn ò láyọ̀ lé. “Ìdààmú” máa bá wọn, wọ́n á sì máa bẹ̀rù pé àwọn lè kú torí pé irú àwọn nǹkan yẹn ò ṣẹlẹ̀ rí. (Sef. 1:14, 15) Nǹkan máa nira gan-an fáwa ìránṣẹ́ Jèhófà nígbà yẹn. Torí pé a kì í ṣe apá kan ayé, wọ́n tún máa fojú pọ́n wa. Kódà, ó ṣeé ṣe ká má ní àwọn ohun ìgbẹ́mìíró àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì. Ọjọ́ pẹ́ tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti ń múra wa sílẹ̀ ká lè jẹ́ olóòótọ́ jálẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà. (Mát. 24:45) Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ ẹ jẹ́ ká wo ọ̀kan lára wọn, ìyẹn àwọn àpéjọ agbègbè tá a ṣe lọ́dún 2016 sí 2018. Láwọn àpéjọ yẹn, wọ́n gbà wá níyànjú láti túbọ̀ láwọn ànímọ́ táá jẹ́ kígbàgbọ́ wa lágbára bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé. w19.10 14 ¶2; 16 ¶10; 17 ¶12
Tuesday, February 16
Ẹ ò lè máa jẹun lórí “tábìlì Jèhófà” àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.—1 Kọ́r. 10:21.
Tá a bá ti lè jẹ oúnjẹ kan, tá a sì gbé e mì, a ò lè pinnu bí oúnjẹ náà ṣe máa ṣiṣẹ́ lára wa. Tó bá sì yá, àwọn èròjà tó wà nínú ẹ̀ máa wọnú ara wa lọ. Tá a bá ń jẹ oúnjẹ tó dáa, ara wa máa le dáadáa, tó bá sì jẹ́ oúnjẹ tí kò dáa là ń jẹ, ó máa ṣàkóbá fún ìlera wa. Lóòótọ́ a lè má tètè mọ̀, àmọ́ bó pẹ́ bó yá ó máa hàn. Lọ́nà kan náà, a lè pinnu irú eré ìnàjú tá a máa wò. Àmọ́ ká má gbàgbé pé tá a bá ti wò ó tán, a ò lè pinnu ipa tó máa ní lórí wa. Tá a bá yan eré ìnàjú tó dáa, a máa gbádùn ẹ̀, àmọ́ tó bá jẹ́ pé èyí tí kò dáa la yàn láàyò, ó máa kó bá wa. (Jém. 1:14, 15) A lè má tètè mọ àkóbá tó máa ṣe, àmọ́ bó pẹ́ bó yá ó máa hàn. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi kìlọ̀ fún wa pé: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká; torí pé ẹni tó bá ń fúnrúgbìn nítorí ara rẹ̀ máa ká ìdíbàjẹ́ látinú ara rẹ̀.” (Gál. 6:7, 8) Àbí ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká yẹra fún gbogbo eré ìnàjú tí Jèhófà kórìíra.—Sm. 97:10. w19.10 30 ¶12-14
Wednesday, February 17
Ẹ máa fara wé Ọlọ́run, bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìfẹ́.—Éfé. 5:1, 2.
Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó yọ̀ǹda Ọmọ rẹ̀ láti kú fún wa. (Jòh. 3:16) Báwo la ṣe lè máa fìfẹ́ hàn bíi ti Jèhófà? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá mọyì àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tá a sì kà wọ́n sí ẹni ọ̀wọ́n. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kí inú wa máa dùn tí “àgùntàn tó sọ nù” tàbí tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (Sm. 119:176; Lúùkù 15:7, 10) A tún lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tá a bá ń fara wa jìn fún wọn, pàápàá nígbà ìṣòro. (1 Jòh. 3:17) Jésù pàṣẹ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ. (Jòh. 13:34, 35) Òfin tuntun ni òfin yẹn torí pé ó yàtọ̀ sírú ìfẹ́ tí Òfin Mósè ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní síra wọn. Jésù sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun nífẹ̀ẹ́ ara wọn bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn. Irú ìfẹ́ yìí gba pé ká ṣe tán àtifi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fáwọn míì. Ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ju ara wa lọ. A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn débi pé àá ṣe tán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ nítorí wọn bíi ti Jésù. w19.05 4 ¶11-13
Thursday, February 18
Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín.—Lúùkù 11:9.
Tá a bá fẹ́ rí ẹ̀mí mímọ́ gbà, a gbọ́dọ̀ máa bẹ̀bẹ̀ fún un léraléra. (Lúùkù 11:13) Àpèjúwe tí Jésù ṣe nínú Lúùkù 11:5-9 jẹ́ ká rí ìdí tí Jèhófà fi máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ọkùnrin tí Jésù sọ nínú àpèjúwe yẹn fẹ́ fi hàn pé òun lẹ́mìí aájò àlejò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ní nǹkan kan nílé, ilẹ̀ sì ti ṣú, ó mọ̀ pé ó yẹ kóun wá nǹkan fi ṣe àlejò òun tó dé lóru yẹn. Jésù sọ pé ọ̀rẹ́ ọkùnrin yẹn dá a lóhùn torí pé onítọ̀hún kò yéé bẹ̀ ẹ́ pé kó fún òun ní búrẹ́dì. Kí ni Jésù fẹ́ fi àpèjúwe yìí kọ́ wa? Tí èèyàn tó jẹ́ aláìpé bá lè ran aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́ torí pé kò yéé bẹ̀ ẹ́, mélòómélòó ni Jèhófà tó jẹ́ Baba wa onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú. Ó dájú pé ó máa dáhùn àdúrà gbogbo àwọn tó bá ń béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ tí wọn ò sì jẹ́ kó sú wọn! Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà tó ò ń gbà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Sm. 10:17; 66:19) Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé láìka gbogbo bí Sátánì ṣe ń halẹ̀ mọ́ wa, tó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti borí wa, àwa la máa ṣẹ́gun ẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. w19.11 13 ¶17-19
Friday, February 19
Ẹ máa bọ̀, ẹ wá síbi tó dá . . . kí ẹ sì sinmi díẹ̀.—Máàkù 6:31.
Jésù mọ̀ pé ó yẹ kí òun àtàwọn àpọ́sítélì òun máa sinmi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ìgbà yẹn àti tòde òní jọra pẹ̀lú ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tí Jésù sọ nínú àkàwé kan tó ṣe. Ọkùnrin yẹn sọ fún ara rẹ̀ pé ohun tó kù fún òun báyìí ni pé kí òun ‘fọkàn balẹ̀, kóun máa jẹ, kóun máa mu, kóun sì máa gbádùn ara òun.’ (Lúùkù 12:19; 2 Tím. 3:4) Lédè míì, ohun tó gbà á lọ́kàn ni bó ṣe máa jẹ̀gbádùn, kó sì máa sinmi. Òdìkejì pátápátá nìyẹn jẹ́ sóhun tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fayé wọn ṣe, torí pé kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa jẹ̀gbádùn ló gbà wọ́n lọ́kàn. Àwa ọmọlẹ́yìn Jésù náà máa ń sapá láti lo àkókò wa lọ́nà tó tọ́ tá ò bá tiẹ̀ sí lẹ́nu iṣẹ́. Yàtọ̀ sí pé ká sinmi, a tún máa ń fi àkókò yẹn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, a sì máa ń lọ sípàdé. Kódà, a kì í fọ̀rọ̀ ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù ṣeré rárá, a gbà pé wọ́n ṣe pàtàkì gan-an ju ohunkóhun míì lọ. Fún ìdí yìí, a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti lọ sípàdé ká sì wàásù. (Héb. 10:24, 25) Tá a bá tiẹ̀ gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, a máa ń rí i dájú pé a ò pa ìpàdé jẹ, a sì máa ń lo gbogbo àǹfààní tó bá yọjú láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run níbikíbi tá a bá wà.—2 Tím. 4:2. w19.12 7 ¶16-17
Saturday, February 20
Ẹ parí ohun tí ẹ ti bẹ̀rẹ̀.—2 Kọ́r. 8:11.
Jèhófà fún wa lómìnira láti pinnu ohun tá a fẹ́ fayé wa ṣe. Ó máa ń kọ́ wa bá a ṣe lè ṣèpinnu tó dáa, tá a bá sì ṣèpinnu tó múnú rẹ̀ dùn, ó máa ń jẹ́ kó yọrí sí rere. (Sm. 119:173) Bá a bá ṣe ń fi àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì sílò, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu. (Héb. 5:14) Tá a bá tiẹ̀ ṣe ìpinnu tó dáa, nígbà míì ó máa ń ṣòro fún wa láti ṣe ohun tá a pinnu. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mélòó kan: Arákùnrin ọ̀dọ́ kan pinnu pé òun fẹ́ ka Bíbélì látòkèdélẹ̀, ó gbìyànjú ẹ̀ wò àmọ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan, ó dáwọ́ ẹ̀ dúró. Arábìnrin kan pinnu pé òun máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ ṣe ló ń fònídónìí-fọ̀ladọ́la. Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kan pinnu pé àwọn fẹ́ túbọ̀ máa ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn ará, àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù, wọn ò tíì bẹ ẹnì kankan wò. Lóòótọ́, àwọn ipò tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí yàtọ̀ síra, àmọ́ ìṣòro kan náà ni gbogbo wọn ní. Àwọn tó ṣe ìpinnu yẹn ò gbé ìgbésẹ̀ lórí ìpinnu tí wọ́n ṣe. w19.11 26 ¶1-2
Sunday, February 21
Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.—Òwe 21:5.
Jésù fi àkókò wa yìí wé bí “àwọn ọjọ́ Nóà” ṣe rí. Bẹ́yin náà ṣe mọ̀, ‘àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira’ là ń gbé yìí. (Mát. 24:37; 2 Tím. 3:1) Kókó yìí làwọn tọkọtaya kan fi sọ́kàn tí wọ́n fi pinnu pé àwọn ò ní tíì bímọ torí wọ́n gbà pé ìyẹn á mú káwọn lè túbọ̀ lo ara wọn fún iṣẹ́ Jèhófà. Àwọn tọkọtaya tó gbọ́n máa ń “ṣírò ohun tó máa ná” wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ pinnu bóyá káwọn bímọ tàbí káwọn má bímọ àti iye ọmọ tí wọ́n máa bí. (Lúùkù 14:28, 29) Àwọn tó ti tọ́mọ darí gbà pé ọmọ títọ́ máa ń náni lówó gan-an. Ìyẹn nìkan kọ́, ó máa ń tánni lókun, ó sì máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kí tọkọtaya bi ara wọn pé: ‘Ṣé àwa méjèèjì la máa ṣiṣẹ́ ká bàa lè gbọ́ bùkátà ìdílé wa? Kí làwọn “bùkátà” tá a gbọ́dọ̀ bójú tó? Tó bá jẹ́ pé àwa méjèèjì ló máa ṣiṣẹ́, ta ló máa bójú tó àwọn ọmọ wa tá ò bá sí nílé? Ta lá máa kọ́ wọn lóhun tí wọ́n á máa ṣe táá sì máa darí èrò wọn?’ Àwọn tọkọtaya tó gbọ́n máa ń fi ìlànà inú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń jíròrò àwọn ìbéèrè yìí. w19.12 23-24 ¶6-7
Monday, February 22
Àwọn yìí . . . la jọ ń ṣiṣẹ́ fún Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ti di orísun ìtùnú fún mi gan-an.—Kól. 4:11.
Ẹ rántí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà kojú onírúurú ìṣòro tó fẹ́rẹ̀ẹ́ gba ẹ̀mí ẹ̀. (2 Kọ́r. 11:23-28) Ó tún fara da ohun tó pè ní ‘ẹ̀gún kan nínú ara rẹ̀,’ tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìṣòro àìlera. (2 Kọ́r. 12:7) Bákan náà, ìdààmú bá a nígbà tí Démà tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pa á tì, “torí [Démà] nífẹ̀ẹ́ ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Tím. 4:10) Ẹni àmì òróró tó nígboyà ni Pọ́ọ̀lù, ó sì máa ń fara ẹ̀ jìn fáwọn míì. Síbẹ̀ àwọn ìgbà kan wà tóun náà rẹ̀wẹ̀sì. (Róòmù 9:1, 2) Kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ tí kò fi bọ́hùn? Kò sí àní-àní pé Jèhófà fún un lókun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (2 Kọ́r. 4:7; Fílí. 4:13) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún lo àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ láti tù ú nínú. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́, ó ní wọ́n jẹ́ “orísun ìtùnú fún [òun] gan-an.” (Kól. 4:11) Lára àwọn tó dárúkọ ni Àrísítákọ́sì, Tíkíkù àti Máàkù. Wọ́n ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́, wọ́n tù ú nínú, wọ́n sì mú kó lè fara da àwọn ìṣòro rẹ̀. w20.01 8 ¶2-3
Tuesday, February 23
Ó ti la ojú inú yín.—Éfé. 1:18.
Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé kò sí bí àwọn tí kì í ṣe ẹni àmì òróró ṣe lè lóye bó ṣe máa ń rí lára àwọn tí a tún bí tàbí àwọn tí a “bí látinú ẹ̀mí,” bí wọ́n tiẹ̀ ṣàlàyé ẹ̀ fún wọn. (Jòh. 3:3-8) Báwo ni ìrònú ẹnì kan ṣe máa ń yí pa dà nígbà tí Ọlọ́run bá fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án? Kí Jèhófà tó fẹ̀mí yan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró láti lọ sọ́run, wọ́n ti nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Wọ́n ń retí ìgbà tí Jèhófà máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò táá sì sọ ayé di Párádísè. Wọ́n tiẹ̀ ti lè máa fojú inú wo bí wọ́n á ṣe kí tẹbítọ̀rẹ́ káàbọ̀ nígbà àjíǹde. Àmọ́ ìrònú wọn yí pa dà lẹ́yìn tí Jèhófà fi ẹ̀mí yàn wọ́n. Kí nìdí? Kì í ṣe torí pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ àtigbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé mọ́. Bákan náà, kì í ṣe torí àwọn ìṣòro àti ìyà tó pọ̀ láyé ló mú kí wọ́n yí ìrònú wọn pa dà. Bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe torí pé wọ́n kàn ṣàdéédéé pinnu pé ayé yìí ò dùn mọ́ àti pé á sú àwọn táwọn bá ń gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti yí ìrònú wọn pa dà, ó sì mú kí wọ́n máa retí àtigbé lọ́run dípò ayé. w20.01 22 ¶9-11
Wednesday, February 24
Kí gbogbo èèyàn máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga.—Róòmù 13:1.
Nínú Òfin Mósè, kì í ṣe ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìjọsìn nìkan làwọn tó wà nípò àṣẹ máa ń bójú tó, wọ́n tún máa ń bójú tó èdèkòyédè tó bá wáyé àtàwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìwà ọ̀daràn. Àmọ́ ní ti “òfin Kristi,” ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìjọsìn nìkan làwọn alàgbà láṣẹ láti bójú tó. (Gál. 6:2) Wọ́n máa ń fi sọ́kàn pé ìjọba nìkan ni Ọlọ́run gbà láyè láti bójú tó àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìwà ọ̀daràn. Ìjọba ló sì láṣẹ láti fìyà tó tọ́ jẹ ẹni tó bá ṣẹ̀, yálà kí wọ́n ní kó sanwó ìtanràn tàbí kí wọ́n fi í sẹ́wọ̀n. (Róòmù 13:2-4) Báwo làwọn alàgbà ṣe máa ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì? Wọ́n máa ń lo Ìwé Mímọ́ láti gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò kí wọ́n sì dórí ìpinnu. Bí wọ́n ṣe ń bójú tó ọ̀rọ̀ náà, wọ́n máa ń fi sọ́kàn pé orí ìfẹ́ la gbé òfin Kristi kà. Ìfẹ́ yìí lá mú káwọn alàgbà fẹ́ mọ ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún ẹni tí wọ́n hùwà ìkà sí. Tí wọ́n bá sì fẹ́ bójú tó ọ̀rọ̀ ẹni tó hùwà àìdáa náà, ìfẹ́ yìí kan náà lá mú káwọn alàgbà ronú lórí ìbéèrè bíi: Ǹjẹ́ ó ronú pìwà dà? Ṣé a lè ràn án lọ́wọ́ láti pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà? w19.05 7 ¶23-24
Thursday, February 25
Mo wà láàyè nítorí Baba.—Jòh. 6:57.
Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ni Orísun ìyè, òun náà ló sì ń pèsè àwọn ohun ìgbẹ́mìíró fún òun nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí. Jésù gbẹ́kẹ̀ lé Baba rẹ̀ pátápátá, Jèhófà náà kò sì já a kulẹ̀ ní ti pé ó pèsè àwọn ohun ìgbẹ́mìíró fún un. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù tí Jèhófà ṣe fún Jésù ni pé ó mú kó lè jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀. (Mát. 4:4) Jèhófà tún ń fún wa lóhun tá a nílò nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó jẹ́ ká mọ irú ẹni tóun jẹ́, ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé, ìdí tó fi dá wa sáyé àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Ó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bó ṣe jẹ́ ká rí òtítọ́, yálà nípasẹ̀ àwọn òbí wa tàbí nípasẹ̀ Ẹlẹ́rìí tó kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Títí di bá a ṣe ń sọ yìí, ó ń lo àwọn alàgbà àtàwọn míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin láti máa ràn wá lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́. Bákan náà, Jèhófà ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ láwọn ìpàdé ìjọ, a sì tún ń gbádùn ìfararora pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa. Àwọn nǹkan yìí àtàwọn nǹkan míì fi hàn pé Jèhófà Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa lápapọ̀ àti lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—Sm. 32:8. w20.02 3 ¶8; 5 ¶13
Friday, February 26
Máa lépa àwọn ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà àti àwọn ohun tó ń gbé ẹnì kejì ró.—Róòmù 14:19.
Àlàáfíà ò lè jọba níbi táwọn èèyàn bá ti ń ṣe ìlara. Nítorí náà, ó yẹ ká fa ẹ̀mí ìlara tu kúrò lọ́kàn wa ká má sì gbìn ín sọ́kàn àwọn míì. Kí làwọn nǹkan pàtó tá a lè ṣe tá ò fi ní mú káwọn míì máa jowú, ká sì jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà? Ìwà àti ìṣe wa lè mú káwọn míì ṣe ohun tó dáa, ó sì lè mú kí wọ́n ṣìwà hù. Ayé yìí ń fẹ́ ká máa “ṣe àṣehàn” àwọn ohun tá a ní. (1 Jòh. 2:16) Àmọ́ ṣe nirú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń fa owú tàbí ìlara. Tá ò bá fẹ́ káwọn míì máa jowú tàbí ṣe ìlara, kò yẹ ká máa sọ̀rọ̀ ṣáá nípa àwọn nǹkan tá a ní tàbí àwọn nǹkan tá a fẹ́ rà. Bákan náà, kò yẹ ká máa fi àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní ṣe fọ́rífọ́rí. Tá a bá ń fọ́nnu nípa iṣẹ́ ìsìn tá a ní, á mú káwọn míì bẹ̀rẹ̀ sí í jowú, kódà ó lè mú kí wọ́n ṣe ìlara. Àmọ́, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tọkàntọkàn, tá à ń fi hàn pé a mọyì wọn, tá a sì ń yìn wọ́n torí iṣẹ́ rere wọn, wọ́n á níyì lójú ara wọn, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan jọba nínú ìjọ. w20.02 18 ¶15-16
Saturday, February 27
Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá.—Róòmù 1:20.
O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tó o bá ń kíyè sí àwọn ohun tó dá. (Ìfi. 4:11) Ronú nípa bí àwọn ewéko àtàwọn ẹranko ṣe ń gbé ọgbọ́n Jèhófà yọ. Fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹ̀yà ara rẹ, wàá sì rí i pé àgbàyanu niṣẹ́ Ọlọ́run. (Sm. 139:14) Máa ronú nípa agbára ńlá tí Jèhófà fi sínú oòrùn tó jẹ́ ẹyọ kan péré nínú ọ̀kẹ́ àìmọye ìràwọ̀. (Àìsá. 40:26) Kò sí àní-àní pé tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ bẹ̀rù Jèhófà, wàá sì mọyì rẹ̀. Àmọ́, kéèyàn gbà pé Jèhófà jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti alágbára wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ohun táá mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Torí náà, tó o bá máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó tún ṣe pàtàkì kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Ó yẹ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an. Rántí ohun tí Bíbélì sọ pé “tí o bá wá a, á jẹ́ kí o rí òun.” (1 Kíró. 28:9) Jèhófà sọ pé ‘mo ti fà ọ́ mọ́ra.’ (Jer. 31:3) Bó o ṣe túbọ̀ ń mọyì gbogbo ohun tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. w20.03 4 ¶6-7
Sunday, February 28
Torí pé [a] rí iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí gbà, a kò juwọ́ sílẹ̀.—2 Kọ́r. 4:1.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ ní ti pé iṣẹ́ ìwàásù ló fi ṣe àkọ́múṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó wà lẹ́nu ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì nílùú Kọ́ríńtì, kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ àgọ́ pípa. Ó ṣe iṣẹ́ náà kó lè fi bójú tó ara rẹ̀ kó bàa lè wàásù fún àwọn ará Kọ́ríńtì “lọ́fẹ̀ẹ́.” (2 Kọ́r. 11:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, kò fi iṣẹ́ ìwàásù jáfara, kódà gbogbo ọjọ́ Sábáàtì ló máa ń wàásù. Lẹ́yìn tí nǹkan yí pa dà díẹ̀ fún Pọ́ọ̀lù, ó wá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Bíbélì sọ pé: “Ọwọ́ Pọ́ọ̀lù dí gan-an, ó ń jẹ́rìí fún àwọn Júù láti fi ẹ̀rí hàn pé Jésù ni Kristi náà.” (Ìṣe 18:3-5; 2 Kọ́r. 11:9) Nígbà tó yá, wọ́n sé Pọ́ọ̀lù mọ́lé fún ọdún méjì nílùú Róòmù, síbẹ̀ ó máa ń wàásù fáwọn tó bá wá kí i, ó sì máa ń kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ. (Ìṣe 28:16, 30, 31) Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. w19.04 4 ¶9