January
Saturday, January 1
Láti kékeré jòjòló lo ti mọ ìwé mímọ́, èyí tó lè mú kí o di ọlọ́gbọ́n kí o lè rí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.—2 Tím. 3:15.
Ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Tímótì kọ́ látinú Ìwé Mímọ́ ló mú kó nígbàgbọ́. Torí náà, ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì jẹ́ káwọn nǹkan tó ò ń kọ́ dá ẹ lójú. Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tó jóòótọ́ tó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú. Àkọ́kọ́, ó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà ló dá ohun gbogbo láyé àti lọ́run. (Ẹ́kís. 3:14, 15; Héb. 3:4; Ìfi. 4:11) Ìkejì, ó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì. (2 Tím. 3:16, 17) Ìkẹta, ó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà ní àwùjọ àwọn èèyàn kan tó ń jọ́sìn rẹ̀ lábẹ́ ìdarí Kristi, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni àwùjọ náà. (Àìsá. 43:10-12; Jòh. 14:6; Ìṣe 15:14) Kò dìgbà tó o bá di igi ìwé tàbí àká ìmọ̀ káwọn nǹkan yìí tó dá ẹ lójú. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o lo “agbára ìrònú” rẹ láti jẹ́ káwọn nǹkan yìí túbọ̀ dá ẹ lójú.—Róòmù 12:1. w20.07 10 ¶8-9
Sunday, January 2
A ò gbà kí àwọn eéṣú náà pa wọ́n, àmọ́ kí wọ́n dá wọn lóró fún oṣù márùn-ún.—Ìfi. 9:5.
Àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìfihàn yẹn sọ nípa àwọn eéṣú tí ojú wọn dà bíi ti èèyàn, tí wọ́n sì dé “ohun tó dà bí adé tí wọ́n fi wúrà ṣe.” (Ìfi. 9:7) Bíbélì sọ pé “àwọn èèyàn [àwọn ọ̀tá Ọlọ́run] tí kò ní èdìdì Ọlọ́run ní iwájú orí wọn nìkan” ni wọ́n dá lóró fún oṣù márùn-ún gbáko, ìyẹn iye àkókò tí eéṣú máa ń lò láyé. (Ìfi. 9:4) Àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ yìí jẹ́ ká rí i pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ ẹni àmì òróró ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣàpẹẹrẹ. Wọ́n ń fìgboyà kéde ìdájọ́ Jèhófà sórí ayé èṣù yìí, ìyẹn ò sì bá àwọn èèyàn ayé lára mu. Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé eéṣú tí Jóẹ́lì 2:7-9 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kì í ṣe ọ̀kan náà pẹ̀lú eéṣú tó wà nínú ìwé Ìfihàn? Ohun tá à ń sọ gan-an nìyẹn. Nínú Bíbélì, kì í ṣe ohun àjèjì pé kí wọ́n lo ohun kan ṣoṣo láti ṣàpẹẹrẹ nǹkan ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nínú Ìfihàn 5:5, Bíbélì pe Jésù ní “Kìnnìún ẹ̀yà Júdà” nígbà tí 1 Pétérù 5:8 pe Èṣù ní “kìnnìún tó ń ké ramúramù.” w20.04 3 ¶8; 5 ¶10
Monday, January 3
Ojú Jèhófà wà níbi gbogbo, ó ń ṣọ́ ẹni burúkú àti ẹni rere.—Òwe 15:3.
Hágárì ìránṣẹ́ Sáráì hùwà òmùgọ̀ lẹ́yìn tó di ìyàwó Ábúrámù. Nígbà tí Hágárì lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fojú burúkú wo Sáráì torí pé kò bímọ. Ọ̀rọ̀ náà le débi pé ṣe ni Sáráì lé Hágárì kúrò nílé. (Jẹ́n. 16:4-6) Tá a bá fojú èèyàn lásán wò ó, ó lè jọ pé agbéraga èèyàn ni Hágárì àti pé ìyà tó tọ́ sí i nìyẹn. Àmọ́, ojú tí Jèhófà fi wo Hágárì yàtọ̀ síyẹn. Ó rán áńgẹ́lì rẹ̀ sí i. Nígbà tí áńgẹ́lì náà rí i, ó tún ojú ìwòye ẹ̀ ṣe, ó sì bù kún un. Hágárì wá mọ̀ pé Jèhófà ti ń wo òun, ó sì mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sóun. Ìyẹn mú kó pe Jèhófà ní “Ọlọ́run tó ń ríran, . . . ẹni tó ń rí mi lóòótọ́.” (Jẹ́n. 16:7-13) Kí ni Jèhófà kíyè sí nípa Hágárì? Jèhófà mọ ipò àtilẹ̀wá rẹ̀ àtàwọn nǹkan tó ti fara dà. Lóòótọ́ Jèhófà ò dá Hágárì láre pé kò bọ̀wọ̀ fún Sáráì, síbẹ̀ ó dájú pé Jèhófà gba tiẹ̀ rò. w20.04 16 ¶8-9
Tuesday, January 4
Mo ti sá eré ìje náà dé ìparí.—2 Tím. 4:7.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé gbogbo àwa Kristẹni tòótọ́ là ń sá eré ìje. (Héb. 12:1) Yálà a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, bóyá ara wa mókun tàbí kò mókun, gbogbo wa pátá la gbọ́dọ̀ sá eré náà, ká sì fara dà á dópin tá a bá fẹ́ rí èrè tí Jèhófà ṣèlérí gbà. (Mát. 24:13) Ẹnu Pọ́ọ̀lù gba ọ̀rọ̀ tó sọ torí pé òun alára ti “sá eré ìje náà dé ìparí.” (2 Tím. 4:7, 8) Àmọ́, eré ìje wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ gan-an? Àwọn ìgbà kan wà tí Pọ́ọ̀lù lo àwọn eré tí wọ́n máa ń ṣe nílẹ̀ Gíríìsì àtijọ́ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì. (1 Kọ́r. 9:25-27; 2 Tím. 2:5) Kódà nínú ìwé tó kọ sáwọn ìjọ kan, ó fi ìgbésí ayé àwa Kristẹni wé ti àwọn sárésáré. (1 Kọ́r. 9:24; Gál. 2:2; Fílí. 2:16) Ìgbà tẹ́nì kan bá ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà tó sì ṣèrìbọmi ló bẹ̀rẹ̀ eré ìje náà. (1 Pét. 3:21) Ìgbà tí Jèhófà bá fún onítọ̀hún ní èrè ìyè àìnípẹ̀kun ló tó sá eré náà dópin.—Mát. 25:31-34, 46; 2 Tím. 4:8. w20.04 26 ¶1-3
Wednesday, January 5
Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra ogun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀.—Éfé. 6:13.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Olóòótọ́ ni Olúwa, yóò fún yín lókun, yóò sì dáàbò bò yín kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (2 Tẹs. 3:3) Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá? Jèhófà ti fún wa ní ìhámọ́ra ogun tó máa dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ Sátánì. (Éfé. 6:13-17) Ohun tí Jèhófà fún wa yìí lágbára, ó sì gbéṣẹ́ gan-an! Àmọ́ kó tó lè dáàbò bò wá, a gbọ́dọ̀ máa lo ọ̀kọ̀ọ̀kan ìhámọ́ra tí Jèhófà fún wa yìí. Òtítọ́ tá a fi di inú wa lámùrè ni òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lò ó? Torí pé Sátánì ni “baba irọ́.” (Jòh. 8:44) Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń parọ́, ó sì ti ṣi “gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà”! (Ìfi. 12:9) Àmọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì ò ní jẹ́ kí Sátánì ṣì wá lọ́nà. Báwo la ṣe lè lo àmùrè tàbí bẹ́líìtì ìṣàpẹẹrẹ yìí? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, tá à ń sìn ín “ní ẹ̀mí àti òtítọ́,” tá a sì jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.—Jòh. 4:24; Éfé. 4:25; Héb. 13:18. w21.03 26-27 ¶3-5
Thursday, January 6
Ó tún máa wọ ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́.—Dán. 11:41.
Ohun tó jẹ́ kí ilẹ̀ náà ṣàrà ọ̀tọ̀ ni pé ibẹ̀ ni àwọn èèyàn ti máa ń ṣe ìjọsìn tòótọ́. Látìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Kristẹni, “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́” náà kì í ṣe orílẹ̀-èdè kan pàtó. Ìyẹn sì bọ́gbọ́n mu torí pé ibi gbogbo láyé làwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà wà. Lónìí, “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́” náà ni Párádísè tẹ̀mí táwọn èèyàn Ọlọ́run wà. Lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe nínú Párádísè tẹ̀mí yìí ni pé wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà láwọn ìpàdé wọn, wọ́n sì ń wàásù nípa Jèhófà fáwọn èèyàn. Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọba àríwá ti wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́.” Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìjọba Násì lórílẹ̀-èdè Jámánì jẹ́ ọba àríwá, pàápàá nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ọba yìí wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́” ní ti pé ó ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì pa ọ̀pọ̀ lára wọn. Bákan náà, lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì nígbà tí ìjọba Soviet Union di ọba àríwá, ọba náà wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́” ní ti pé òun náà ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì kó ọ̀pọ̀ lára wọn lọ sí ìgbèkùn. w20.05 13 ¶7-8
Friday, January 7
Àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ májẹ̀mú rẹ̀.—Sm. 25:14.
Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn tó di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run kí Jésù tó wá sáyé. Ábúráhámù lo ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Lẹ́yìn ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún kan tí Ábúráhámù kú, Jèhófà pè é ní “ọ̀rẹ́ mi.” (Àìsá. 41:8) Èyí jẹ́ ká rí i pé kò sóhun tó lè ya Jèhófà àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kódà ikú ò lè yà wọ́n. Lójú Jèhófà, Ábúráhámù ṣì wà láàyè. (Lúùkù 20:37, 38) Àpẹẹrẹ ẹlòmíì ni Jóòbù. Ìṣojú ọ̀kẹ́ àìmọye áńgẹ́lì ni Jèhófà ti fi Jóòbù yangàn. Jèhófà sọ pé “olódodo àti olóòótọ́ èèyàn ni, ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú.” (Jóòbù 1:6-8) Kí ni Jèhófà sọ nípa Dáníẹ́lì, tóun náà sin Jèhófà nílẹ̀ àwọn abọ̀rìṣà fún nǹkan bí ọgọ́rin (80) ọdún? Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn áńgẹ́lì sọ fún un pé ó “ṣeyebíye gan-an” lójú Ọlọ́run. (Dán. 9:23; 10:11, 19) Ó dá wa lójú pé Jèhófà ń fojú sọ́nà de ìgbà tó máa jí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde.—Jóòbù 14:15. w20.05 26-27 ¶3-4
Saturday, January 8
Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.—Sm. 119:68.
Akẹ́kọ̀ọ́ kan lè mọ àwọn òfin Ọlọ́run, kódà ó lè mọyì wọn. Àmọ́ ṣéyẹn máa mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kó sì fi tọkàntọkàn ṣe ohun tó fẹ́? Ẹ rántí pé Ádámù àti Éfà lóye òfin Jèhófà, àmọ́ wọn ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó fún wọn lófin náà. (Jẹ́n. 3:1-6) Torí náà, kì í ṣe àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa tẹnu mọ́ tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà wúlò gan-an, wọ́n sì ń ṣe wá láǹfààní. (Sm. 119:97, 111, 112) Àmọ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tó lè gbà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ dá wọn lójú pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó fún wa lófin. Torí náà, a lè bi akẹ́kọ̀ọ́ wa pé: “Kí lo rò pé ó mú kí Jèhófà ṣòfin pé ká ṣe báyìí tàbí ká má ṣe báyìí? Báwo nìyẹn ṣe jẹ́ ká mọ irú Ẹni tó jẹ́?” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa wọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́kàn tá a bá mú kí wọ́n mọyì Jèhófà kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ orúkọ mímọ́ rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn òfin Jèhófà nìkan ni, kódà gbogbo ọkàn ni wọ́n fi máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó fún wa lófin náà. Èyí á mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára, wọ́n á sì lè fara da àdánwò èyíkéyìí tó bá yọjú.—1 Kọ́r. 3:12-15. w20.06 10 ¶10-11
Sunday, January 9
Ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára láti gbọ́rọ̀, kí wọ́n [sì] lọ́ra láti sọ̀rọ̀.—Jém. 1:19.
Ó yẹ ká mú sùúrù torí pé kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ máa kọ́fẹ pa dà nípa tẹ̀mí. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti fìgbà kan rí jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ sọ pé, léraléra làwọn alàgbà àtàwọn míì bẹ àwọn wò káwọn tó pa dà sínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Nancy tó ń gbé nílẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Kì í ṣe iṣẹ́ kékeré ni ọ̀rẹ́ mi kan ṣe kí n tó pa dà sínú ìjọ. Ṣe ló mú mi bí ọmọ ìyá. Ó máa ń rán mi létí àwọn nǹkan dáadáa tá a ti ṣe sẹ́yìn. Ó máa ń mú sùúrù, ó sì máa ń tẹ́tí sí mi tí mo bá ń sọ ẹ̀dùn ọkàn mi. Yàtọ̀ síyẹn kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó sì máa ń fún mi nímọ̀ràn nígbà tó bá yẹ. Ká sòótọ́, ọ̀rẹ́ gidi tó ṣe tán láti ranni lọ́wọ́ nígbàkigbà ni arábìnrin náà.” Ṣe lọ̀rọ̀ ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn dà bíi ẹni tó fara pa, tá a bá fi ìgbatẹnirò hàn sí i, ṣe ló dà bí ìgbà tá a fún ẹni náà ní oògùn táá mú kára tù ú. Ẹnì kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ ṣì lè máa rántí ohun tẹ́nì kan ṣe sí i lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, kíyẹn sì máa bí i nínú. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè ṣòro fún un láti pa dà sínú ìjọ. Àwọn kan lè ronú pé àwọn alàgbà ò bójú tó ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn bó ṣe yẹ. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nílò ẹni tó máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn táá sì gba tiwọn rò. w20.06 26 ¶10-11
Monday, January 10
Ẹ . . . ti ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.—1 Jòh. 2:14.
Gbogbo ìgbà tó o bá borí àdánwò lá túbọ̀ máa rọrùn fún ẹ láti ṣe ohun tó tọ́. Máa rántí pé Sátánì ló ń jẹ́ káwọn èèyàn máa ní èrò òdì nípa ìbálòpọ̀. Torí náà tí o kò bá gba èrò burúkú yìí láyè, wàá “ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.” A gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. A sì ń sapá ká má bàa dẹ́ṣẹ̀ sí i. Àmọ́ tá a bá ṣẹ̀, ó yẹ ká jẹ́wọ́ ohun tá a ṣe fún Jèhófà nínú àdúrà. (1 Jòh. 1:9) Tá a bá sì dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo, ó yẹ ká lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà tí Jèhófà yàn láti bójú tó wa. (Jém. 5:14-16) Síbẹ̀ kò yẹ ká máa ronú ṣáá nípa ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Baba wa onífẹ̀ẹ́ ti pèsè ìràpadà nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ká lè rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà. Jèhófà ti sọ pé òun máa dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Torí náà, kò sóhun tó ní ká má fi ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ sin Jèhófà.—1 Jòh. 2:1, 2, 12; 3:19, 20. w20.07 22-23 ¶9-10
Tuesday, January 11
Ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà.—Sm. 36:9.
Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló wà, àmọ́ kò ṣe é bíi pé òun dá wà. Ìdí sì ni pé Jèhófà ò nílò kí ẹnikẹ́ni wà pẹ̀lú òun kó tó lè láyọ̀. Síbẹ̀, ó fẹ́ káwọn míì wà kí wọ́n sì láyọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan. (1 Jòh. 4:19) Ẹni tí Jèhófà kọ́kọ́ dá ni Jésù Ọmọ rẹ̀. Ó wá tipasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ “dá gbogbo ohun mìíràn” títí kan gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run. (Kól. 1:16) Inú Jésù dùn gan-an pé òun bá Bàbá òun ṣiṣẹ́. (Òwe 8:30) Inú àwọn áńgẹ́lì náà dùn bí wọ́n ṣe ń wo Jèhófà tó ń dá àwọn nǹkan. Ìṣojú wọn ni Jèhófà àti Jésù tó jẹ́ Àgbà Òṣìṣẹ́ ṣe dá ayé àti ọ̀run. Kí làwọn áńgẹ́lì ṣe nígbà tí Jèhófà ń dá àwọn nǹkan? Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà dá ayé, Bíbélì sọ pé wọ́n ń ‘hó yèè, wọ́n sì ń yin’ Jèhófà. Ohun kan náà ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbà tí Jèhófà dá àwọn nǹkan tó kù láyé títí kan àwa èèyàn tó dá kẹ́yìn. (Jóòbù 38:7; Òwe 8:31, àlàyé ìsàlẹ̀) Gbogbo nǹkan tí Jèhófà dá ló fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni, ó sì nífẹ̀ẹ́.—Sm. 104:24; Róòmù 1:20. w20.08 14 ¶1-2
Wednesday, January 12
Gbogbo orílẹ̀-èdè . . . máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.—Mát. 24:9.
Jèhófà dá wa lọ́nà tó fi máa ń wù wá káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ wa, káwa náà sì fìfẹ́ hàn sáwọn míì. Torí náà tẹ́nì kan bá kórìíra wa, ó máa ń dùn wá, kódà ó lè mú kẹ́rù máa bà wá. Arákùnrin kan sọ pé: “Ìgbà kan wà táwọn sójà lù mí, tí wọ́n rọ̀jò èébú lé mi lórí, tí wọ́n sì halẹ̀ mọ́ mi torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ìyẹn mú kí ẹ̀rù bà mí gan-an, kí ojú sì tì mí.” Ká sòótọ́, inú wa kì í dùn tí wọ́n bá kórìíra wa. Àmọ́ kò yà wá lẹ́nu torí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn máa kórìíra wa. Kí nìdí táwọn èèyàn fi kórìíra àwa ọmọlẹ́yìn Jésù? Ìdí ni pé bíi ti Jésù, a “kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòh. 15:17-19) Torí náà, a máa ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba àtàwọn tó wà nípò àṣẹ, àmọ́ a kì í jọ́sìn wọn tàbí àwọn àmì tí wọ́n gbé kalẹ̀, bí àsíá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Jèhófà nìkan là ń jọ́sìn torí a gbà pé Òun nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso aráyé bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sátánì àti “ọmọ” rẹ̀ kò gbà bẹ́ẹ̀. (Jẹ́n. 3:1-5, 15) A tún ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ìrètí tí aráyé ní àti pé láìpẹ́ Ìjọba náà máa pa gbogbo ìjọba ayé yìí run. (Dán. 2:44; Ìfi. 19:19-21) Ìròyìn ayọ̀ lèyí jẹ́ fáwọn ọlọ́kàn tútù, àmọ́ ó máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn ẹni burúkú. w21.03 20 ¶1-2
Thursday, January 13
A mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run la ti wá.—1 Jòh. 5:19.
Jèhófà mọyì àwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ gan-an, iṣẹ́ pàtàkì ló sì gbé fún wọn. Wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n, wọ́n nígbàgbọ́, wọ́n nítara, wọ́n nígboyà, wọ́n lawọ́, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ rere. (Lúùkù 8:2, 3; Ìṣe 16:14, 15; Róòmù 16:3, 6; Fílí. 4:3; Héb. 11:11, 31, 35) Inú wa dùn pé a ní àwọn àgbàlagbà láàárín wa. Wọ́n lè ní àwọn àìlera kan tí wọ́n ń bá yí nítorí ọjọ́ ogbó. Síbẹ̀, wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì ń lo gbogbo okun wọn láti fún àwọn míì níṣìírí, kí wọ́n sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Tẹ̀gàn ni hẹ̀, àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní ń ṣe wá láǹfààní. Inú Jèhófà ń dùn sí wọn gan-an, àwa náà sì mọyì wọn. (Òwe 16:31) Àwọn míì tó tún wà nínú ìjọ ni àwọn ọ̀dọ́. Inú ayé tí Sátánì ń darí tó sì kún fún èrò àti ìwà tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n ń gbé, síbẹ̀ wọn ò jẹ́ kó kéèràn ràn wọ́n. Ó máa ń wú wa lórí gan-an bá a ṣe ń rí i táwọn ọ̀dọ́ yìí ń dáhùn nípàdé, tí wọ́n ń lọ sóde ẹ̀rí, tí wọ́n sì ń fìgboyà sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì. Torí náà ẹ̀yin ọ̀dọ́, a fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé ẹ wúlò nínú ìjọ, a sì mọyì yín gan-an!—Sm. 8:2. w20.08 21-22 ¶9-11
Friday, January 14
Mò ń rán yín jáde bí àgùntàn sáàárín àwọn ìkookò.—Mát. 10:16.
Ó ṣeé ṣe ká kojú ohun tó dà bí ìjì nígbà tá a di akéde, tá a sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé a ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́nà wo? Àwọn ìdílé wa lè ta kò wá, àwọn ọ̀rẹ́ wa lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn tá à ń wàásù fún sì lè má tẹ́tí sí wa. Kí ló máa jẹ́ kó o nígboyà? Àkọ́kọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jésù ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù yìí látọ̀run. (Jòh. 16:33; Ìfi. 14:14-16) Láfikún síyẹn, jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó o ní pé Jèhófà máa bójú tó ẹ túbọ̀ jinlẹ̀. (Mát. 6:32-34) Bí ìgbàgbọ́ rẹ ṣe ń lágbára sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa nígboyà. Ìwọ náà fi hàn pé ìgbàgbọ́ tó lágbára lo ní nígbà tó o sọ fún tẹbí-tọ̀rẹ́ rẹ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́, o sì ti ń lọ sípàdé wọn. Kò sí àní-àní pé o ti ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nígbèésí ayé ẹ kó o lè máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò. Ohun tó o ṣe yìí fi hàn pé o nígbàgbọ́ àti ìgboyà. Bó o ṣe túbọ̀ ń nígboyà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé “Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí o bá lọ.”—Jóṣ. 1:7-9. w20.09 5 ¶11-12
Saturday, January 15
Jèhófà fún un ní ìsinmi.—2 Kíró. 14:6.
Àpẹẹrẹ àtàtà ni Ọba Ásà tó bá di pé kéèyàn gbára lé Jèhófà pátápátá. Kì í ṣe ìgbà tí nǹkan nira fún un nìkan ló fi gbogbo ọkàn ẹ̀ sin Jèhófà, ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí àlàáfíà wà. Bíbélì ròyìn pé àtikékeré ni “Ásà [ti ń] fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà.” (1 Ọba 15:14) Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Ásà gbà fi hàn pé gbogbo ọkàn lòun fi ń jọ́sìn Jèhófà ni pé ó pa gbogbo ìjọsìn èké run nílẹ̀ Júdà. Bíbélì sọ pé: “Ó mú àwọn pẹpẹ àjèjì àti àwọn ibi gíga kúrò, ó fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́, ó sì gé àwọn òpó òrìṣà lulẹ̀.” (2 Kíró. 14:3, 5) Kódà, ó tún yọ Máákà ìyá rẹ̀ àgbà kúrò ní ipò ìyá ọba. Kí nìdí? Torí pé ìyá náà ń bọ̀rìṣà, ó sì tún ń mú káwọn míì máa ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Ọba 15:11-13) Kì í ṣe pé Ásà pa ìsìn èké run nìkan, ó tún mú káwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà pa dà máa jọ́sìn Jèhófà bí Jèhófà ṣe fẹ́. Torí náà, Jèhófà bù kún Ásà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì mú kí àlàáfíà jọba nílẹ̀ náà. Kódà, fún odindi ọdún mẹ́wàá àkọ́kọ́ tí Ásà fi ṣàkóso, “kò sí ìyọlẹ́nu ní ilẹ̀ náà.”—2 Kíró. 14:1, 4, 6. w20.09 14 ¶2-3
Sunday, January 16
Tímótì, máa ṣọ́ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ.—1 Tím. 6:20.
Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń fi àwọn ohun ìní wa tó ṣeyebíye síkàáwọ́ àwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń tọ́jú owó wa sí báǹkì torí a gbà pé wọ́n á bá wa tọ́jú ẹ̀, kò sẹ́ni tó máa jí i, kò sì ní sọ nù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán Tímótì létí ohun iyebíye tí Jèhófà fi síkàáwọ́ rẹ̀, ìyẹn ìmọ̀ tó péye nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún fún Tímótì láǹfààní láti “wàásù ọ̀rọ̀ náà” kó sì “ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere.” (2 Tím. 4:2, 5) Pọ́ọ̀lù wá rọ Tímótì pé kó máa ṣọ́ ohun tí Jèhófà fi sí ìkáwọ́ rẹ̀. Bíi ti Tímótì, Jèhófà ti fi àwọn ohun iyebíye kan síkàáwọ́ àwa náà. Jèhófà ti jẹ́ ká ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Òtítọ́ yìí ṣeyebíye gan-an torí pé ó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àti bá a ṣe lè ní ojúlówó ayọ̀. Torí pé a gba àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí gbọ́, a sì ń fi wọ́n sílò, a ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké àti ìṣekúṣe tó gbayé kan.—1 Kọ́r. 6:9-11. w20.09 26 ¶1-3
Monday, January 17
Ẹ . . . mọ irú ẹni tí a dà láàárín yín àti nítorí yín.—1 Tẹs. 1:5.
Ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ rí i pé o nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ Bíbélì, ó sì dá ẹ lójú. Ìyẹn á mú kí òun náà nífẹ̀ẹ́ ohun tó ń kọ́. Láwọn ìgbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó mọ àwọn àǹfààní tó ò ń rí bó o ṣe ń fàwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé ẹ. Ìyẹn á jẹ́ kóun náà rí i pé àwọn ìlànà Bíbélì wúlò, ó sì máa ṣe òun láǹfààní. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, máa sọ ìrírí àwọn tó nírú ìṣòro tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ní tí wọ́n sì borí ẹ̀. O lè mú ẹnì kan nínú ìjọ yín tí ìrírí ẹ̀ máa ṣe akẹ́kọ̀ọ́ rẹ láǹfààní lọ sọ́dọ̀ ẹ̀. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ rí bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó pé kéèyàn máa fi ìlànà Bíbélì sílò. Tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ bá ti ṣègbéyàwó, ṣé ọkọ tàbí aya rẹ̀ náà ń kẹ́kọ̀ọ́? Tẹ́ni náà kò bá tíì máa kẹ́kọ̀ọ́, fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ ọ́. Gba akẹ́kọ̀ọ́ rẹ níyànjú pé kó máa sọ ohun tó ń kọ́ fún tẹbítọ̀rẹ́.—Jòh. 1:40-45. w20.10 16 ¶7-9
Tuesday, January 18
Kí o máa fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ léraléra.—Diu. 6:7.
Jósẹ́fù àti Màríà fi ìlànà Ọlọ́run tọ́ Jésù débi tó fi rí ojúure Ọlọ́run bó ṣe ń dàgbà. (Diu. 6:6, 7) Jósẹ́fù àti Màríà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, ohun tó sì jẹ wọ́n lógún ni báwọn ọmọ wọn náà ṣe máa nírú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ fún Jèhófà. Àwọn nǹkan tẹ̀mí ni Jósẹ́fù àti Màríà máa ń ṣe nínú ìdílé wọn. Ó dájú pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n máa ń lọ sípàdé nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárẹ́tì, wọ́n sì máa ń lọ sí àjọyọ̀ Ìrékọjá ní Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún. (Lúùkù 2:41; 4:16) Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa sọ ìtàn àwọn èèyàn Ọlọ́run fún Jésù àtàwọn àbúrò rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń dé àwọn ibi tí Bíbélì mẹ́nu kàn. Báwọn ọmọ wọn ṣe ń pọ̀ sí i, ó ṣeé ṣe kó má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún Jósẹ́fù àti Màríà láti máa ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí déédéé. Àmọ́ torí pé ìjọsìn Jèhófà ló gbawájú láyé wọn, wọn ò jẹ́ kí nǹkan míì gbà wọ́n lọ́kàn. w20.10 28 ¶8-9
Wednesday, January 19
Ẹ́sírà ti múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ láti wádìí nínú Òfin Jèhófà . . . àti láti máa kọ́ àwọn èèyàn ní àwọn ìlànà inú rẹ̀.—Ẹ́sírà 7:10.
Tó o bá máa tẹ̀ lé ẹnì kan lọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á dáa kó o múra ibi tẹ́ ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀. Arákùnrin Dorin tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe sọ pé: “Inú mi máa ń dùn tẹ́ni tá a jọ ṣiṣẹ́ bá ti múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀, torí pé ìyẹn á jẹ́ kó lè sọ ohun tó máa ṣe akẹ́kọ̀ọ́ náà láǹfààní.” Yàtọ̀ síyẹn, akẹ́kọ̀ọ́ náà máa kíyè sí pé ẹ̀yin méjèèjì múra sílẹ̀ dáadáa, ìyẹn á sì fún un níṣìírí láti máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ká tiẹ̀ wá sọ pé o ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ bó o ṣe fẹ́, gbìyànjú kó o mọ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú ibi tẹ́ ẹ fẹ́ kà. Àdúrà tá a máa ń gbà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe pàtàkì gan-an, torí náà á dáa kó o ti ronú ohun tó o máa sọ tí wọ́n bá ní kó o gbàdúrà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, àdúrà rẹ á nítumọ̀. (Sm. 141:2) Hanae tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Japan rántí àdúrà tí arábìnrin tó tẹ̀ lé ẹni tó ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ gbà. Ó sọ pé: “Mo kíyè sí i pé ó ní àjọṣe tó lágbára pẹ̀lú Jèhófà, ó sì wù mí kí n fara wé e. Yàtọ̀ síyẹn, ara tù mí nígbà tó dárúkọ mi nínú àdúrà náà.” w21.03 9-10 ¶7-8
Thursday, January 20
Mọ́kàn le! . . . O máa jẹ́rìí ní Róòmù.—Ìṣe 23:11.
Jésù fi Pọ́ọ̀lù lọ́kàn balẹ̀ pé ó máa dé Róòmù. Àmọ́, àwọn Júù kan tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbìmọ̀ pọ̀ láti lúgọ de Pọ́ọ̀lù kí wọ́n sì pa á. Nígbà tí ọ̀gágun Róòmù kan tó ń jẹ́ Kíláúdíù Lísíà gbọ́ nípa ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe, ó dáàbò bo Pọ́ọ̀lù. Láìjáfara, Kíláúdíù yan ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun, ó sì ní kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù lọ sí Kesaríà. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Gómìnà Fẹ́líìsì pàṣẹ pé “kí wọ́n máa ṣọ́ [Pọ́ọ̀lù] ní ààfin Hẹ́rọ́dù.” Ó dájú pé ọwọ́ àwọn apààyàn yẹn ò ní lè tẹ Pọ́ọ̀lù níbẹ̀. (Ìṣe 23:12-35) Fẹ́sítọ́ọ̀sì ló rọ́pò Fẹ́líìsì bíi gómìnà. Torí pé Fẹ́sítọ́ọ̀sì “ń wá ojú rere àwọn Júù,” ó bi Pọ́ọ̀lù pé: “Ṣé o fẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí a lè dá ẹjọ́ rẹ níbẹ̀ níwájú mi?” Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n pa òun tóun bá lọ sí Jerúsálẹ́mù. Torí náà, ó sọ pé: “Mo ké gbàjarè sí Késárì!” Fẹ́sítọ́ọ̀sì sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Késárì lo ké gbàjarè sí; ọ̀dọ̀ Késárì ni wàá sì lọ.” Láìpẹ́, Pọ́ọ̀lù máa lọ sí Róòmù, ọwọ́ àwọn Júù tó ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á ò sì ní lè tẹ̀ ẹ́.—Ìṣe 25:6-12. w20.11 13 ¶4; 14 ¶8-10
Friday, January 21
Ọkàn wa . . . lè dá wa lẹ́bi.—1 Jòh. 3:20.
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, gbogbo wa la máa ń dá ara wa lẹ́bi. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè máa dá ara wọn lẹ́bi nítorí àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àwọn míì sì máa ń dá ara wọn lẹ́bi nítorí àṣìṣe tí wọ́n ṣe lẹ́yìn ìrìbọmi. (Róòmù 3:23) Òótọ́ ni pé a máa ń fẹ́ ṣe ohun tó tọ́, àmọ́ “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jém. 3:2; Róòmù 7:21-23) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú wa kì í dùn tá a bá ń dára wa lẹ́bi, ó láǹfààní tiẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi, ó lè mú ká ṣàtúnṣe sí ìwà kan tá a hù, á sì mú ká pinnu pé a ò ní ṣe irú ẹ̀ mọ́. (Héb. 12:12, 13) Lọ́wọ́ kejì, ẹnì kan lè máa dára ẹ̀ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ, lédè míì kó máa dára ẹ̀ lẹ́bi lẹ́yìn tó ti ronú pìwà dà, tí Jèhófà sì ti jẹ́ kó dá a lójú pé òun dárí jì í. Irú èrò bẹ́ẹ̀ léwu gan-an. (Sm. 31:10; 38:3, 4) Kò sì yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé inú Sátánì máa dùn tá a bá rẹ̀wẹ̀sì tá a sì dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ti dárí jì wá!—Fi wé 2 Kọ́ríńtì 2:5-7, 11. w20.11 27 ¶12-13
Saturday, January 22
Ó dájú pé lásán ni mo pa ọkàn mi mọ́, tí mo sì wẹ ọwọ́ mi mọ́ pé mo jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀.—Sm. 73:13.
Ọmọ Léfì tó kọ Sáàmù yìí ń jowú àwọn agbéraga àti àwọn ẹni burúkú torí pé lójú ẹ̀, wọ́n ń gbádùn ìgbésí ayé wọn. (Sm. 73:2-9, 11-14) Lérò tiẹ̀, gbogbo nǹkan ni wọ́n ní, wọ́n lọ́lá, wọ́n lọ́là, ayé yẹ wọ́n, ọkàn wọn sì balẹ̀. Tí ọmọ Léfì yìí bá máa borí ìlara àti ìrẹ̀wẹ̀sì, ó ṣe pàtàkì kó máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Torí pé ó ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn ẹ̀ balẹ̀, inú ẹ̀ sì dùn. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn [Jèhófà], kò sí ohun míì tó wù mí ní ayé.” (Sm. 73:25) Ẹ má ṣe jẹ́ káwa náà jowú àwọn ẹni burúkú tó jọ pé wọ́n ń gbádùn ayé wọn. Tó bá tiẹ̀ dà bíi pé wọ́n ń gbádùn ara wọn, ojú ayé lásán ni, kò sì lè tọ́jọ́. (Oníw. 8:12, 13) Tá a bá ń jowú wọn, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, tá ò bá sì ṣọ́ra a lè fi Jèhófà sílẹ̀. Tó bá jọ pé o ti ń jowú àwọn ẹni burúkú, tètè ṣe ohun tí ọmọ Léfì yẹn ṣe. Fi ìmọ̀ràn Jèhófà sílò, kó o sì bá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kẹ́gbẹ́. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ju ohunkóhun míì lọ, wàá ní ojúlówó ayọ̀, o ò sì ní kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí “ìyè tòótọ́.”—1 Tím. 6:19. w20.12 19 ¶14-16
Sunday, January 23
Ìṣòro ibẹ̀ ni pé a ò mọ ohun tó yẹ ká fi sínú àdúrà bó ṣe yẹ ká ṣe, àmọ́ ẹ̀mí fúnra rẹ̀ ń bá wa bẹ̀bẹ̀ nígbà tí a wà nínú ìrora inú lọ́hùn-ún.—Róòmù 8:26.
Tó o bá ń sọ ẹ̀dùn ọkàn ẹ fún Jèhófà, má gbàgbé láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó ṣe pàtàkì ká máa rántí àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa, kódà lásìkò tí nǹkan nira fún wa gan-an. Àmọ́ nígbà míì, ẹ̀dùn ọkàn wa lè pọ̀ débi pé a ò ní mọ bá a ṣe lè sọ ọ́ fún Jèhófà. Kí la lè ṣe nírú àsìkò bẹ́ẹ̀? Ká rántí pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa kódà kó jẹ́ pé gbogbo ohun tá a lè sọ ò ju ‘Jọ̀ọ́, ràn mí lọ́wọ́.’ (2 Kíró. 18:31) Àwọn ìlànà Jèhófà ni kó o máa tẹ̀ lé, kì í ṣe tara ẹ. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ Ṣ.S.K., àwọn ará Ásíríà bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn Júdà. Káwọn Júù yẹn má bàa bọ́ sábẹ́ àjàgà àwọn ará Ásíríà, wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Íjíbítì tó jẹ́ abọ̀rìṣà. (Àìsá. 30:1, 2) Àmọ́, Jèhófà kìlọ̀ fún wọn pé ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa yọrí sí kò ní dáa. (Àìsá. 30:7, 12, 13) Nípasẹ̀ Àìsáyà, Jèhófà jẹ́ káwọn èèyàn náà mọ ohun tí wọ́n á ṣe tí wọn ò fi ní kó síṣòro, tí ọkàn wọn á sì balẹ̀. Ó ní: “Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé” Jèhófà.—Àìsá. 30:15b. w21.01 3-4 ¶8-9
Monday, January 24
Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a gbé èdìdì lé, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000).—Ìfi. 7:4.
Jèhófà máa san àwọn arákùnrin Kristi tó jẹ́ ẹni àmì òróró lẹ́san torí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́, á sì mú kí wọ́n di ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run. (Ìfi. 20:6) Inú Jèhófà àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tó wà lọ́run máa dùn gan-an nígbà tí ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) bá pé tí wọ́n sì gba èrè wọn lọ́run. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n jẹ́ ọba àti àlùfáà, ó tún rí àwọn míì tó múnú ẹ̀ dùn, ìyẹn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tí wọ́n la Amágẹ́dọ́nì já. “Ogunlọ́gọ̀ èèyàn” yìí yàtọ̀ sí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) torí pé wọ́n pọ̀ gan-an, a ò sì mọye tí wọ́n máa jẹ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. (Ìfi. 7:9, 10) Wọ́n “wọ aṣọ funfun,” ní ti pé wọ́n wà “láìní àbààwọ́n” nínú ayé Sátánì, wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti Kristi. (Jém. 1:27) Wọ́n polongo pé ohun tí Jèhófà àti Jésù tó jẹ́ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run ṣe ló mú káwọn rí ìgbàlà. Bákan náà, wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ dání, tó fi hàn pé tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n gbà pé Jésù ni Ọba tí Jèhófà yàn.—Fi wé Jòhánù 12:12, 13. w21.01 15-16 ¶6-7
Tuesday, January 25
Ìrẹ̀lẹ̀ rẹ . . . sọ mí di ẹni ńlá.—2 Sám. 22:36.
Ọkùnrin kan lè jẹ́ olórí ìdílé gidi tó bá ń fara wé bí Jèhófà àti Jésù ṣe ń lo àṣẹ tí wọ́n ní. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Jèhófà ló gbọ́n jù láyé àti lọ́run, síbẹ̀ ó máa ń fetí sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (Jẹ́n. 18:23, 24, 32) Ẹni pípé ni Jèhófà, àmọ́ kò retí pé ká máa ṣe nǹkan lọ́nà pípé. Dípò bẹ́ẹ̀, ó máa ń ran àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ tá a jẹ́ aláìpé lọ́wọ́ ká lè ṣàṣeyọrí. (Sm. 113:6, 7) Kódà, Bíbélì pe Jèhófà ní “olùrànlọ́wọ́.” (Sm. 27:9; Héb. 13:6) Ọba Dáfídì gbà pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jèhófà ní ló mú kóun ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ tó gbé fún òun. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jésù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun ni Olúwa àti Aṣáájú fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó fọ ẹsẹ̀ wọn. Jésù sọ pé: “Mo fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín pé, bí mo ṣe ṣe fún yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.” (Jòh. 13:12-17) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù lẹnì kejì tó láṣẹ jù láyé àti lọ́run, kò retí pé káwọn èèyàn ṣe ìránṣẹ́ fún òun, dípò bẹ́ẹ̀ òun ló ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.—Mát. 20:28. w21.02 3-4 ¶8-10
Wednesday, January 26
Ògo àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn.—Òwe 20:29.
Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin tó wà nínú ìjọ wúlò gan-an. Eegun ọ̀dọ́ wà lára yín, ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ sì lè ṣe. Onírúurú ọ̀nà lẹ lè gbà ran àwọn ará lọ́wọ́ nínú ìjọ. Ó dájú pé ó ń wu ẹ̀yin náà pé kẹ́ ẹ di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àmọ́, ó lè máa ṣe yín bíi pé àwọn kan ń fojú ọmọdé wò yín tàbí pé ẹ ti kéré jù láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ ṣì kéré lọ́jọ́ orí, àwọn nǹkan kan wà tẹ́ ẹ lè ṣe báyìí táá mú káwọn tó wà nínú ìjọ fọkàn tán yín kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún yín. Ṣé ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin náà ní àwọn ẹ̀bùn tẹ́ ẹ lè fi ran àwọn míì lọ́wọ́ nínú ìjọ? Ó dájú pé ẹ ní. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ ti kíyè sí i pé àwọn àgbàlagbà kan ò mọ bí wọ́n ṣe lè lo tablet tàbí fóònù wọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ tàbí tí wọ́n bá wà nípàdé. Inú wọn máa dùn gan-an tẹ́ ẹ bá kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè lò ó. Máa ṣe ohun táá múnú Jèhófà Baba rẹ ọ̀run dùn nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe. w21.03 2 ¶1, 3; 7 ¶18
Thursday, January 27
Kálukú ló máa ru ẹrù ara rẹ̀.—Gál. 6:5.
Tí ìyàwó kan bá tiẹ̀ kàwé ju ọkọ ẹ̀ lọ, ojúṣe ọkọ ṣì ni láti múpò iwájú nínú ìjọsìn Jèhófà. (Éfé. 6:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aya kan gbọ́dọ̀ fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀, òun fúnra ẹ̀ gbọ́dọ̀ sapá láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Torí náà, ó gbọ́dọ̀ máa wáyè láti dá kẹ́kọ̀ọ́, kó sì máa ṣàṣàrò. Ìyẹn á mú kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, inú ẹ̀ á sì máa dùn bó ṣe ń fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ rẹ̀. Inú àwọn aya tó ń fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń dùn, ọkàn wọn sì máa ń balẹ̀ ju àwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀ lọ. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Bákan náà, wọ́n máa ń jẹ́ kí ara tu àwọn tó wà nínú ìdílé kí àlàáfíà sì wà nínú ìjọ. (Títù 2:3-5) Kódà, obìnrin ló pọ̀ jù lára àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà lónìí.—Sm. 68:11. w21.02 13 ¶21-23
Friday, January 28
Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.—Jém. 4:8.
Àpẹẹrẹ àtàtà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ tó bá di pé ká nígboyà ká sì fara da ìṣòro. Àwọn ìgbà kan wà tó rẹ̀wẹ̀sì. Àmọ́, ó fara dà á torí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa fún òun lókun. (2 Kọ́r. 12:8-10; Fílí. 4:13) Àwa náà lè nírú ìgboyà àti okun tó ní tá a bá bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. (Jém. 4:10) Ó yẹ kó dá wa lójú pé kì í ṣe Jèhófà ló ń fìyà jẹ wá tá a bá ń kojú ìṣòro. Jémíìsì tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù fi dá wa lójú pé: “Tí àdánwò bá dé bá ẹnikẹ́ni, kó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ló ń dán mi wò.’ Torí a ò lè fi ibi dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jém. 1:13) Tó bá dá wa lójú pé Jèhófà kọ́ ló ń dán wa wò, àá túbọ̀ sún mọ́ Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa. Jèhófà “kì í yí pa dà, . . . kì í sì í sún kiri.” (Jém. 1:17) Ó ran àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro, ó sì dájú pé ohun tó máa ṣe fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa náà nìyẹn. Torí náà, bẹ Jèhófà taratara pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n, ìgbàgbọ́ àti ìgboyà. Á gbọ́ àdúrà rẹ. w21.02 31 ¶19-21
Saturday, January 29
Bí irin ṣe ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ṣe ń pọ́n ọ̀rẹ́ rẹ̀.—Òwe 27:17.
Ọ̀nà kan tó o lè gbà fún akẹ́kọ̀ọ́ ẹ tó ń wá sípàdé níṣìírí ni pé kó o máa fìfẹ́ hàn sí i. (Fílí. 2:4) O ò ṣe sún mọ́ ọn, kó o lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n dáadáa. Jẹ́ kó mọ bí inú ẹ ṣe dùn tó pé ó ń tẹ̀ síwájú. O tún lè béèrè nípa ìdílé ẹ̀, iṣẹ́ ẹ̀ àti bí ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ ṣe ń lọ sí, àmọ́ ṣọ́ra kó o má lọ béèrè ìbéèrè tó lè dójú tì í. Irú àwọn ìjíròrò yìí lè mú kẹ́ ẹ dọ̀rẹ́. Tẹ́ ẹ bá dọ̀rẹ́, á ṣeé ṣe fún ẹ láti ràn án lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú débi táá fi ṣèrìbọmi. Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú, tó sì ń ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ, ṣe ohun táá jẹ́ kó mọ̀ pé kì í ṣe ẹni tuntun mọ́ láàárín wa. O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń fẹ̀mí aájò àlejò hàn sí i. (Héb. 13:2) Lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ti di akéde, o lè sọ fún un pé kẹ́ ẹ jọ jáde òde ẹ̀rí. Arákùnrin Diego tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo di akéde, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ní kí n bá àwọn jáde òde ẹ̀rí, ìyẹn sì jẹ́ kí n mọ̀ wọ́n dáadáa. Bí mo ṣe túbọ̀ ń mọ̀ wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni mò ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, ìyẹn sì mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti Jésù.” w21.03 12 ¶15-16
Sunday, January 30
Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnikẹ́ni.—Róòmù 12:17.
Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn. (Mát. 5:44, 45) Ṣé ìyẹn rọrùn? Rárá o! Àmọ́, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà lè mú kó ṣeé ṣe. Ẹ̀mí mímọ́ máa jẹ́ ká ní ìfẹ́, sùúrù, inú rere, ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu. (Gál. 5:22, 23) Àwọn ànímọ́ yìí máa jẹ́ ká lè fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wa. Ọ̀pọ̀ àwọn tó kórìíra wa tẹ́lẹ̀ ló ti yí pa dà torí pé ọkọ, ìyàwó, ọmọ tàbí aládùúgbò tó jẹ́ Kristẹni fi àwọn ànímọ́ yìí hàn. Kódà ọ̀pọ̀ àwọn alátakò yìí ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, tó bá ṣòro fún ẹ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn tó kórìíra ẹ torí pé ò ń sin Jèhófà, gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Kó o sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé kò sígbà tó o ṣègbọràn sí Ọlọ́run tó o máa kábàámọ̀. (Òwe 3:5-7) Ìkórìíra burú, ó sì máa ń dunni, àmọ́ ìfẹ́ ló máa mú ká borí rẹ̀. Ó lè yí ọkàn àwọn tó kórìíra wa pa dà. Ó sì máa ń múnú Jèhófà dùn, kódà táwọn alátakò wa ò bá yí pa dà, a ṣì lè láyọ̀. w21.03 23 ¶13; 24 ¶15, 17
Monday, January 31
Orílẹ̀-èdè kan ti gòkè wá sí ilẹ̀ mi, ó lágbára gan-an, kò sì lóǹkà.—Jóẹ́lì 1:6.
Wòlíì Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọ ogun kan máa gbéjà ko ilẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Jóẹ́lì 2:1, 8, 11) Jèhófà sọ pé òun máa lo “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ ogun” òun (ìyẹn àwọn ọmọ ogun Bábílónì) láti fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìgbọràn. (Jóẹ́lì 2:25) Bíbélì pe àwọn ọmọ ogun náà ní “àwọn ará àríwá” torí pé apá àríwá làwọn ará Bábílónì máa gbà wá gbéjà ko ilẹ̀ Ísírẹ́lì. (Jóẹ́lì 2:20) Bíbélì fi àwọn ọmọ ogun náà wé ọ̀wọ́ eéṣú tí wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Jóẹ́lì sọ nípa àwọn ọmọ ogun náà pé: “Kálukú wọn ń tọ ọ̀nà tirẹ̀. . . . Wọ́n rọ́ wọnú ìlú, . . . Wọ́n gun orí àwọn ilé, wọ́n sì gba àwọn ojú fèrèsé wọlé bí olè.” (Jóẹ́lì 2:8, 9) Ṣé ẹ lè fojú inú wo bó ṣe máa rí? Ibi yòówù kéèyàn yíjú sí, àwọn ọmọ ogun yẹn ló máa rí. Kò síbi téèyàn lè forí pa mọ́ sí tí ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Bábílónì kò ní tẹ̀ ẹ́. Bí ìgbà tí eéṣú bá ya bo ìlú làwọn ará Bábílónì (ìyẹn àwọn ará Kálídíà) ṣe ya wọ ìlú Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bíbélì sọ pé: “Ọba àwọn ará Kálídíà dìde sí wọn, . . . kò ṣàánú ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin, arúgbó tàbí aláàárẹ̀.”—2 Kíró. 36:17. w20.04 5 ¶11-12