ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es22 ojú ìwé 17-26
  • February

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • February
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Tuesday, February 1
  • Wednesday, February 2
  • Thursday, February 3
  • Friday, February 4
  • Saturday, February 5
  • Sunday, February 6
  • Monday, February 7
  • Tuesday, February 8
  • Wednesday, February 9
  • Thursday, February 10
  • Friday, February 11
  • Saturday, February 12
  • Sunday, February 13
  • Monday, February 14
  • Tuesday, February 15
  • Wednesday, February 16
  • Thursday, February 17
  • Friday, February 18
  • Saturday, February 19
  • Sunday, February 20
  • Monday, February 21
  • Tuesday, February 22
  • Wednesday, February 23
  • Thursday, February 24
  • Friday, February 25
  • Saturday, February 26
  • Sunday, February 27
  • Monday, February 28
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
es22 ojú ìwé 17-26

February

Tuesday, February 1

Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.​—Fílí. 2:3.

Sún mọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kó o lè túbọ̀ mọ̀ wọ́n. Máa bá wọn sọ̀rọ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé, bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, tó bá sì ṣeé ṣe ní kí wọ́n wá jẹun nílé ẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o lè wá rí i pé ojú ló ń ti arábìnrin kan tó o rò pé kò kóni mọ́ra. Bákan náà, o lè wá rí i pé arákùnrin kan tó o rò pé ó nífẹ̀ẹ́ owó nífẹ̀ẹ́ àlejò gan-an, o sì lè wá mọ̀ pé ìdílé kan tó máa ń pẹ́ dé ìpàdé ń fara da ọ̀pọ̀ inúnibíni. (Jóòbù 6:29) Àmọ́ o, ìyẹn ò wá ní ká máa “tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀.” (1 Tím. 5:13) Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì ká mọ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin dáadáa, ká sì mọ ohun tó ń mú kí wọ́n máa ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe. Tó o bá túbọ̀ mọ arákùnrin tàbí arábìnrin kan tí inú ẹ̀ máa ń bí ẹ, ó ṣeé ṣe kó o bẹ̀rẹ̀ sí í gba tiẹ̀ rò. Ó máa ń gba ìsapá kéèyàn tó lè mọ àwọn ará dáadáa. Síbẹ̀, tá a bá fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò tó ní ká ṣí ọkàn wa sílẹ̀ pátápátá, Jèhófà tó nífẹ̀ẹ́ “onírúurú èèyàn” là ń fara wé.​—1 Tím. 2:3, 4; 2 Kọ́r. 6:11-13. w20.04 16-17 ¶10-12

Wednesday, February 2

Kò sí ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.​—Jòh. 15:13.

Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó rán àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ létí pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Ó mọ̀ pé tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n á wà níṣọ̀kan, á sì rọrùn fún wọn láti fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wọn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni tó wà ní ìjọ Tẹsalóníkà. Àtìgbà tí wọ́n ti dá ìjọ náà sílẹ̀ làwọn èèyàn ti ń ṣenúnibíni sí wọn. Síbẹ̀, àwọn ará yẹn fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ ní ti pé wọ́n fara dà á, wọn ò sì yéé nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (1 Tẹs. 1:3, 6, 7) Bó ti wù kó rí, Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn. (1 Tẹs. 4:9, 10) Ìfẹ́ tí wọ́n ní yìí ló jẹ́ kí wọ́n máa tu àwọn tó sorí kọ́ nínú, kí wọ́n sì máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. (1 Tẹs. 5:14) Nínú lẹ́tà kejì tí Pọ́ọ̀lù kọ sí wọn ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, ó hàn pé wọ́n fi ìmọ̀ràn náà sílò. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi sọ fún wọn pé: “Ìfẹ́ tí ẹ ní sí ara yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ . . . ń pọ̀ sí i.” (2 Tẹs. 1:3-5) Ìfẹ́ tí wọ́n ní ló mú kí wọ́n lè fara da ìṣòro àti inúnibíni. w21.03 22 ¶11

Thursday, February 3

Ká . . . máa fi ìfaradà sá eré ìje tó wà níwájú wa.​—Héb. 12:1.

Káwa Kristẹni tó lè rí èrè ìyè àìnípẹ̀kun gbà, a gbọ́dọ̀ tọ ọ̀nà ìgbésí ayé tí Kristi fi lélẹ̀. (Ìṣe 20:24; 1 Pét. 2:21) Àmọ́, Sátánì àtàwọn tó ń ṣèfẹ́ rẹ̀ kò fẹ́ ká máa tọ ọ̀nà yẹn, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n fẹ́ ká máa ṣe bíi tiwọn. (1 Pét. 4:4) Wọ́n ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ pé ìgbésí ayé wa kò nítumọ̀, pé tiwọn ló sàn jù torí pé àwọn wà lómìnira. Àmọ́ ohun tí wọ́n sọ kì í ṣòótọ́. (2 Pét. 2:19) Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa tọ ọ̀nà tó tọ́! Sátánì fẹ́ kí gbogbo wa ṣíwọ́ rírìn lójú ọ̀nà tó há èyí “tó lọ sí ìyè” ká sì bọ́ sí ọ̀nà gbòòrò, ìyẹn ọ̀nà tí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn ayé yìí ń rìn. Ọ̀nà gbòòrò yìí làwọn èèyàn mọ̀ jù, ó sì rọrùn láti rìn. Àmọ́ Bíbélì sọ pé ó “lọ sí ìparun.” (Mát. 7:13, 14) Tá a bá fẹ́ máa rìn nìṣó lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè ká má sì kúrò níbẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ká sì máa tẹ́tí sí i. w20.04 26 ¶1; 27 ¶5, 7

Friday, February 4

Mò ń pàrọwà fún yín . . . pé kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀, kí ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ máa dúpẹ́, . . . ká lè máa gbé ìgbé ayé tó pa rọ́rọ́ nìṣó pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn, bí a ti ń fi gbogbo ọkàn wa sin Ọlọ́run.​—1 Tím. 2:​1, 2.

Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ti wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́.” (Dán. 11:41) Kí ló fi hàn bẹ́ẹ̀? Lọ́dún 2017, ọba àríwá tuntun yìí fòfin de iṣẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà, ó sì ju àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kan sẹ́wọ̀n. Ó tún fòfin de àwọn ìtẹ̀jáde wa títí kan Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ohun míì tó tún ṣe ni pé, ó gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà títí kan àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa. Pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ṣe yìí, lọ́dún 2018 Ìgbìmọ̀ Olùdarí jẹ́ kó ṣe kedere pé orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ni ọba àríwá. Àmọ́ láìka gbogbo bó ṣe ń fojú pọ́n àwọn èèyàn Jèhófà tó sì ń ṣenúnibíni sí wọn, àwọn èèyàn Jèhófà kò bá ìjọba jà, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò wá bí wọ́n ṣe máa dojú ìjọba dé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni wọ́n ń ṣe pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún “gbogbo àwọn tó wà ní ipò gíga,” ní pàtàkì táwọn ìjọba bá fẹ́ pinnu bóyá kí wọ́n fún wa lómìnira láti jọ́sìn. w20.05 14 ¶9

Saturday, February 5

Máa kíyè sí ara rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ nígbà gbogbo.​—1 Tím. 4:16.

Ẹ̀yin òbí, káwọn ọmọ yín tó lè sọ òtítọ́ di tiwọn, wọ́n gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, kó sì dá wọn lójú pé òtítọ́ ni Bíbélì fi kọ́ni. Tí ẹ bá máa kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ẹ̀kọ́ òtítọ́ gbọ́dọ̀ yé ẹ̀yin náà dáadáa. Torí náà, ẹ gbọ́dọ̀ máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kẹ́ ẹ sì máa ṣàṣàrò lórí ẹ̀. Ìgbà yẹn lẹ tó lè kọ́ àwọn ọmọ yín pé káwọn náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kẹ́ ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n ṣe lè lo àwọn ohun èlò tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ́ ẹ ṣe ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yín níta. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ yín á mọyì Jèhófà àtàwọn tí Jèhófà ń lò láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí, ìyẹn “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mát. 24:45-47) Kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Bíbélì nìkan ló yẹ kẹ́ ẹ máa kọ́ àwọn ọmọ yín. Ẹ máa kọ́ wọn ní “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” débi tí òye wọn gbé e dé. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn á lágbára.​—1 Kọ́r. 2:10. w20.07 11 ¶10, 12-13

Sunday, February 6

Jèhófà kórìíra oníbékebèke, ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ Rẹ̀ tímọ́tímọ́.​—Òwe 3:32.

Ṣé Jèhófà láwọn ọ̀rẹ́ lórí ilẹ̀ ayé lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni, kódà wọ́n lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù ló mú kí wọ́n di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Ìyẹn ló mú kí Jèhófà fún wa láǹfààní láti yara wa sí mímọ́ fún òun, ká sì ṣèrìbọmi. Tẹ́nì kan bá gbé àwọn ìgbésẹ̀ yìí, á dara pọ̀ mọ́ àwọn mílíọ̀nù èèyàn tó ti yara wọn sí mímọ́, tí wọ́n ṣèrìbọmi, tí wọ́n sì ti di ‘ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́’ pẹ̀lú Ẹni tó ga jù lọ láyé àti lọ́run. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Bíi ti Ábúráhámù àti Jóòbù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà fún ohun tó lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún, àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka iye ọdún tá a ti ń sin Jèhófà bọ̀ nínú ayé burúkú yìí. Bíi ti Dáníẹ́lì, a gbọ́dọ̀ mọyì bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kó sì ṣe pàtàkì sí wa ju ẹ̀mí wa lọ. (Dán. 6:7, 10, 16, 22) Ó dájú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò èyíkéyìí, ìyẹn á sì mú kí okùn ọ̀rẹ́ wa túbọ̀ lágbára.​—Fílí. 4:13. w20.05 27 ¶5-6

Monday, February 7

Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀.​—Sm. 86:11.

Ìgbà kan wà tí Dáfídì tajú kán rí ìyàwó oníyàwó níbi tó ti ń wẹ̀. Kò sí àní-àní pé ó mọ òfin Jèhófà tó sọ pé: “Ojú rẹ ò . . . gbọ́dọ̀ wọ ìyàwó ọmọnìkejì rẹ.” (Ẹ́kís. 20:17) Síbẹ̀, kò gbójú kúrò. Èyí mú kó máa ronú bóyá kóun ṣe ohun tóun fẹ́ pẹ̀lú Bátí-ṣébà tàbí kóun ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí Dáfídì ti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó sì ń bẹ̀rù rẹ̀, síbẹ̀ ó gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè. Èyí mú kó ṣèṣekúṣe, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú àjálù bá àwọn míì, títí kan ìdílé òun alára. (2 Sám. 11:1-5, 14-17; 12:7-12) Jèhófà bá Dáfídì wí, ó sì pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. (2 Sám. 12:13; Sm. 51:2-4, 17) Dáfídì kò jẹ́ gbàgbé wàhálà àti ìṣòro tóun kojú torí pé òun jẹ́ kí ọkàn òun pínyà. Ohun tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 86:11 tún lè túmọ̀ sí: “Má ṣe jẹ́ kí n ní ìpínyà ọkàn.” Ṣé Jèhófà dáhùn àdúrà yẹn? Ó dájú pé ó ṣe bẹ́ẹ̀, torí nígbà tó yá, Jèhófà pe Dáfídì ní ọkùnrin tó “fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.”​—1 Ọba 11:4; 15:3. w20.06 11 ¶12-13

Tuesday, February 8

Mo fi . . . okùn ìfẹ́ fà wọ́n mọ́ra.​—Hós. 11:4.

Bíbélì fi ìfẹ́ tí Jèhófà ní fáwa èèyàn rẹ̀ wé okùn. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká ṣàkàwé ẹ̀ báyìí: Jẹ́ ká sọ pé o wà lójú agbami tó ń ru gùdù, ohun kan wá ṣẹlẹ̀ tó mú kó o máa rì, o ò sì fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wẹ̀. Lẹnì kan bá ju ohun kan sí ẹ táá jẹ́ kó o léfòó lójú omi. Kò sí àní-àní pé wàá mọyì ẹ̀ gan-an, wàá sì di ohun náà mú kó o má bàa rì. Àmọ́ ìyẹn nìkan ò tó, torí tó o bá pẹ́ jù lójú omi, o lè kú torí pé òtútù lè mú ẹ kọjá bó ṣe yẹ. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ ká sọ pé ẹnì kan ju okùn sí ẹ, tó sì ń fà ẹ́ kó o lè bọ́ sínú ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbẹ̀mí là? Ó dájú pé inú ẹ máa dùn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bí Jèhófà ṣe sọ nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní, ó ‘fi okùn ìfẹ́ fa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ra.’ Lónìí, bọ́rọ̀ àwọn tó fi ìjọ sílẹ̀ tí wọ́n sì ń tinú ìṣòro kan bọ́ sí òmíì ṣe rí lára Jèhófà nìyẹn. Ó fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, òun sì ń fẹ́ kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ òun. Ṣé wàá jẹ́ kí Jèhófà lò ẹ́ láti fìfẹ́ hàn sí wọn? Ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ káwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé àwa náà mọyì wọn. w20.06 27 ¶12-13

Wednesday, February 9

Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fara da àdánwò.​—Jém. 1:12.

Nígbà tí wọ́n pa Sítéfánù, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì “tú ká lọ sí gbogbo agbègbè Jùdíà àti Samáríà,” kódà àwọn kan sá lọ sí Sápírọ́sì àti Áńtíókù. (Ìṣe 7:58–8:1; 11:19) Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ìṣòro làwọn ọmọlẹ́yìn yẹn kojú, síbẹ̀ wọ́n ń fìtara wàásù ní gbogbo ibi tí wọ́n lọ, wọ́n sì ń dá ìjọ sílẹ̀ láwọn ilẹ̀ tí Róòmù ń ṣàkóso. (1 Pét. 1:1) Àmọ́ kékeré làwọn ìṣòro yẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìṣòro tí wọ́n ṣì máa kojú. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bíi 50 S.K., Olú Ọba Kíláúdíù pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Júù fi ìlú Róòmù sílẹ̀. Torí náà, ó di dandan pé kí àwọn Júù tó ti di Kristẹni fi ilé wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì kó lọ síbòmíì. (Ìṣe 18:1-3) Nígbà tó di nǹkan bíi 61 S.K., àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé àwọn èèyàn pẹ̀gàn àwọn Kristẹni ní gbangba, wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn lẹ́rù. (Héb. 10:32-34) Yàtọ̀ síyẹn, bíi tàwọn èèyàn yòókù, àwọn Kristẹni náà fara da ipò òṣì àti àìsàn.​—Róòmù 15:26; Fílí. 2:25-27. w21.02 26-27 ¶2-4

Thursday, February 10

Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ń bínú gidigidi, ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù fún òun.​—Ìfi. 12:12.

Tá a bá sapá kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára, kò sóhun tí Sátánì tàbí àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ máa ṣe táá mú ká kúrò nínú òtítọ́. (2 Jòh. 8, 9) A mọ̀ pé àwọn èèyàn ayé máa kórìíra wa. (1 Jòh. 3:13) Jòhánù rán wa létí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòh. 5:19) Bí ayé búburú yìí ṣe ń lọ sópin, ṣe ni inú á túbọ̀ máa bí Sátánì. Kì í ṣe ìṣekúṣe tàbí irọ́ táwọn apẹ̀yìndà ń pa nìkan ni Sátánì máa ń fẹ́ fi mú wa. Ó tún máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣe inúnibíni sí wa gan-an. Ó mọ̀ pé àsìkò díẹ̀ ló kù fóun, torí náà gbogbo ọ̀nà ló ń wá kó lè dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró kó sì ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́. Kò yà wá lẹ́nu nígbà náà pé wọ́n ń fòfin de iṣẹ́ wa láwọn orílẹ̀-èdè kan. Síbẹ̀, àwọn ará wa lọkùnrin àti lóbìnrin láwọn orílẹ̀-èdè yẹn ò sọ̀rètí nù, wọ́n ń fara dà á. Wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ohun yòówù kí Sátánì ṣe sáwa èèyàn Jèhófà, àwa la máa ṣẹ́gun! w20.07 24 ¶12-13

Friday, February 11

Ìyè àìnípẹ̀kun ni ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fúnni nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.​—Róòmù 6:23.

Nígbà tí Jèhófà dá ayé, ohun tó fẹ́ ni pé kí gbogbo ayé jẹ́ Párádísè káwa èèyàn sì máa gbé nínú ẹ̀ títí láé. Àmọ́ nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Baba wọn ọ̀run, àwọn àtàwọn ọmọ wọn bẹ̀rẹ̀ sí í kú. (Róòmù 5:12) Kí wá ni Jèhófà ṣe? Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà sọ bó ṣe máa dá aráyé nídè. (Jẹ́n. 3:15) Jèhófà ṣèlérí pé òun máa pèsè ìràpadà táá jẹ́ kí àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ìyẹn lá mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yàn bóyá àwọn máa sin Jèhófà káwọn sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun àbí àwọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Jòh. 3:16; 1 Kọ́r. 15:21, 22) Nígbà tí Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ bá máa jí àwọn òkú dìde, a lè gbà pé kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan náà ni gbogbo wọn máa jíǹde. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé tí gbogbo òkú bá jíǹde lẹ́ẹ̀kan náà, èrò á ti pọ̀ jù láyé, nǹkan á sì rí rúdurùdu. A sì mọ̀ pé Jèhófà kì í ṣe nǹkan rúdurùdu. Ó mọ̀ pé táwa èèyàn bá máa gbé ní àlàáfíà, nǹkan gbọ́dọ̀ wà létòlétò.​—1 Kọ́r. 14:33. w20.08 14 ¶3; 15 ¶5

Saturday, February 12

Máa kíyè sí ara rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ nígbà gbogbo.​—1 Tím. 4:16.

Akẹ́kọ̀ọ́ kan gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ìdí tá a fi ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ni pé a fẹ́ kó di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ìgbésẹ̀ kan wà tí akẹ́kọ̀ọ́ kan máa gbé títí táá fi ṣèrìbọmi. Àkọ́kọ́, ó gbọ́dọ̀ mọ Jèhófà, kó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kó sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Jòh. 3:16; 17:3) Lẹ́yìn náà, á ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, á sì di ọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ. (Héb. 10:24, 25; Jém. 4:8) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, akẹ́kọ̀ọ́ náà á pa àwọn ìwà rẹ̀ àtijọ́ tì, á sì ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. (Ìṣe 3:19) Bákan náà, ìgbàgbọ́ tó ní á mú kó máa sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn míì. (2 Kọ́r. 4:13) Lẹ́yìn ìyẹn, á yara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, á sì ṣèrìbọmi. (1 Pét. 3:21; 4:2) Ẹ wo bí inú gbogbo ìjọ ṣe máa dùn lọ́jọ́ tó bá ṣèrìbọmi! Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń gbé ìgbésẹ̀ kan tẹ̀ lé òmíì, máa gbóríyìn fún un, kó o sì máa fún un níṣìírí kó lè máa tẹ̀ síwájú. w20.10 17-18 ¶12-13

Sunday, February 13

Tí ẹsẹ̀ bá sọ pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe apá kan ara,” ìyẹn ò sọ pé kì í ṣe apá kan ara.​—1 Kọ́r. 12:15.

Tó o bá ń fi ara ẹ wé àwọn míì nínú ìjọ, o lè máa ronú pé o ò já mọ́ nǹkan kan. Òótọ́ ni pé àwọn kan lè mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa, àwọn míì lè mọ bí wọ́n ṣe ń ṣètò nǹkan gan-an, káwọn míì sì mọ bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn lọ́nà tó gbéṣẹ́. Ó ṣeé ṣe kó o ronú pé o ò lè ṣe bíi tiwọn láé. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ nìyẹn, èyí fi hàn pé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, o sì mọ̀wọ̀n ara ẹ. (Fílí. 2:3) Àmọ́, ó tún yẹ kó o kíyè sára. Tó o bá ń fi ara ẹ wé àwọn míì nígbà gbogbo, inú ẹ ò ní dùn. Kódà bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò wúlò nínú ìjọ rárá. Jèhófà fún àwọn mélòó kan lára àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní àwọn ẹ̀bùn kan, àmọ́ kì í ṣe ẹ̀bùn kan náà ló fún gbogbo wọn. (1 Kọ́r. 12:4-11) Síbẹ̀ kò sí èyí tí kò wúlò. Lónìí, àwa ò ní irú àwọn ẹ̀bùn àgbàyanu bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ìlànà ibẹ̀ ni pé bí ẹ̀bùn tá a ní bá tiẹ̀ yàtọ̀ síra, gbogbo wa pátá la wúlò fún Jèhófà. w20.08 23 ¶13-15

Monday, February 14

Jèhófà wà lẹ́yìn mi; mi ò ní bẹ̀rù.​—Sm. 118:6.

Tó o bá gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kó o nígboyà, Jèhófà máa dáhùn àdúrà rẹ, kò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀. (Ìṣe 4:29, 31) Ìgbà gbogbo lá máa tì ẹ́ lẹ́yìn. Ronú nípa bó ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí àwọn ìṣòro, tó sì fún ẹ lókun láti ṣe àwọn ìyípadà nígbèésí ayé ẹ. Ó dájú pé Ẹni tó mú káwọn èèyàn rẹ̀ la Òkun Pupa já máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. (Ẹ́kís. 14:13) Torí náà, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bíi ti onísáàmù tó sọ ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Jèhófà tún máa ń ran àwọn akéde tuntun lọ́wọ́ kí wọ́n lè nígboyà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Tomoyo. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé, ẹni àkọ́kọ́ tó wàásù fún jágbe mọ́ ọn pé: “Mi ò fẹ́ rí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan nílé mi!” ó sì pa ìlẹ̀kùn dé gbàgà. Tomoyo wá sọ fún ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pé: “Ṣó o gbọ́ nǹkan tó sọ? Mi ò tíì sọ nǹkan kan tó ti mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ìyẹn mà múnú mi dùn o!” Ní báyìí, Tomoyo ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. w20.09 6 ¶13-14

Tuesday, February 15

Ásà ṣe ohun tó dára tó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.​—2 Kíró. 14:2.

Ásà sọ fáwọn èèyàn náà pé Jèhófà ti fún wọn “ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó yí [wọn] ká.” (2 Kíró. 14:6, 7) Ásà ò ronú pé káwọn máa gbádùn ara wọn lásìkò tí àlàáfíà wà yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ìlú tó wà nílẹ̀ Júdà, àwọn ògiri tó yí wọn ká, àwọn ilé gogoro àtàwọn ẹnubodè. Ó sọ fáwọn èèyàn náà pé: “Ilẹ̀ náà ṣì wà ní ìkáwọ́ wa.” Kí ni Ásà ní lọ́kàn? Ohun tó ní lọ́kàn ni pé àwọn èèyàn lè lọ síbi tó wù wọ́n nílẹ̀ tí Jèhófà fún wọn, wọ́n sì lè ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà láìsí pé àwọn ọ̀tá ń yọ wọ́n lẹ́nu. Ó rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n lo àkókò tí àlàáfíà wà yẹn láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Ásà tún lo àkókò àlàáfíà yẹn láti fi kó àwọn ọmọ ogun jọ. (2 Kíró. 14:8) Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọba Ásà mọ̀ pé ojúṣe òun ni láti múra àwọn èèyàn náà sílẹ̀ torí ìṣòro tó lè wáyé lọ́jọ́ iwájú. Ó mọ̀ pé àkókò àlàáfíà yẹn kò ní wà títí láé, bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn. w20.09 15 ¶4-5

Wednesday, February 16

Má ṣe kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀.​—1 Kọ́r. 4:6.

Alàgbà kan lè fẹ́ máa ṣòfin tó rò pé ó máa dáàbò bo àwọn àgùntàn Ọlọ́run. Àmọ́, ìyàtọ̀ wà láàárín àṣẹ táwọn alàgbà ní àti èyí táwọn olórí ìdílé ní. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ti yan àwọn alàgbà ṣe onídàájọ́, ó sì fún wọn láṣẹ láti yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ. (1 Kọ́r. 5:11-13) Lọ́wọ́ kejì, Jèhófà fún àwọn olórí ìdílé láwọn àṣẹ kan tí kò fún àwọn alàgbà. Bí àpẹẹrẹ, ó fún àwọn olórí ìdílé láṣẹ láti ṣòfin nínú ìdílé wọn. (Róòmù 7:2) Olórí ìdílé kan láṣẹ láti pinnu ìgbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa wọlé. Ó tún lẹ́tọ̀ọ́ láti bá àwọn ọmọ ẹ̀ wí tí wọ́n bá rú òfin yẹn. (Éfé. 6:1) Àmọ́, ó yẹ kí olórí ìdílé kan fọ̀rọ̀ lọ ìyàwó rẹ̀ kó tó ṣòfin nínú ilé. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé àwọn méjèèjì ti di “ara kan.”​—Mát. 19:6. w21.02 16-18 ¶10-13

Thursday, February 17

[Ọgbọ́n] ṣeyebíye ju iyùn lọ; kò sí ohun míì tí o fẹ́ tó ṣeé fi wé e.​—Òwe 3:15.

Ọ̀kan lára ohun tó jẹ́ kí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣeyebíye ni pé àwọn onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n jẹ́ “olóòótọ́ ọkàn” nìkan ni Jèhófà jẹ́ kó mọ̀ ọ́n. (Ìṣe 13:48) Àwọn olóòótọ́ ọkàn yìí gbà pé ẹrú olóòótọ́ àti olóye ni Jèhófà ń lò láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lónìí. (Mát. 11:25; 24:45) A ò lè fúnra wa lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí, kò sì sóhun tó ṣeyebíye tó kéèyàn lóye òtítọ́. (Òwe 3:13) Jèhófà tún fún wa láǹfààní láti máa kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa òun àti ohun tóun fẹ́ ṣe fáráyé. (Mát. 24:14) Ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí ṣeyebíye gan-an torí pé ó ń jẹ́ káwọn èèyàn wá di ara ìdílé Jèhófà, ó sì ń fún wọn láǹfààní láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun. (1 Tím. 4:16) Yálà ipò wa gbà wá láyè láti wàásù gan-an tàbí níwọ̀nba, ohun tó jà jù ni pé à ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lásìkò wa yìí. (1 Tím. 2:3, 4) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà jẹ́ ká lè máa bá òun ṣiṣẹ́!​—1 Kọ́r. 3:9. w20.09 26-27 ¶4-5

Friday, February 18

A rí àwọn ará . . . wọ́n sì rọ̀ wá pé ká lo ọjọ́ méje lọ́dọ̀ àwọn.​—Ìṣe 28:14.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń rìnrìn àjò lọ sí Róòmù, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà lo àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, Àrísítákọ́sì àti Lúùkù tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù pinnu láti bá a rìnrìn àjò náà lọ sí Róòmù. Kò sí ibì kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó sọ pé Jésù fara han Àrísítákọ́sì àti Lúùkù tó sì sọ fún wọn pé wọ́n máa dé Róòmù láyọ̀. Síbẹ̀, wọ́n gbà láti fi ẹ̀mí ara wọn wewu, kí wọ́n sì bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò yẹn. Ìgbà tí ìjì ń jà lójú omi tó sì ń bì lu ọkọ̀ wọn ni wọ́n tó mọ̀ pé Jèhófà máa dá ẹ̀mí àwọn sí. Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀ sí Sídónì, Júlíọ́sì gbà kí Pọ́ọ̀lù “lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì ṣìkẹ́ rẹ̀.” (Ìṣe 27:1-3) Nígbà tí wọ́n dé Pútéólì, Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ ‘rí àwọn ará níbẹ̀, wọ́n sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n lo ọjọ́ méje lọ́dọ̀ àwọn.’ Bí àwọn Kristẹni tó wà láwọn ìlú yẹn ṣe ń ṣe Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ lálejò, ó dájú pé Pọ́ọ̀lù á máa fi àwọn ìrírí tó ní gbé àwọn ará náà ró.​—Fi wé Ìṣe 15:2, 3. w20.11 15-16 ¶15-17

Saturday, February 19

Ìfọkànsin Ọlọ́run . . . ní ìlérí ìwàláàyè ní báyìí àti ìlérí ìwàláàyè ti ọjọ́ iwájú.​—1 Tím. 4:8.

Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kẹ́ ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín lọ́rọ̀ àti níṣe pé ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú. Ẹ fi sọ́kàn pé ẹ̀bùn tó dáa jù tẹ́ ẹ lè fún àwọn ọmọ yín ni pé kẹ́ ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ẹ̀kọ́ pàtàkì míì tẹ́ ẹ lè kọ́ wọn ni pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, kí wọ́n máa gbàdúrà déédéé, kí wọ́n máa lọ sípàdé déédéé, kí wọ́n sì máa wàásù déédéé. (1 Tím. 6:6) Lóòótọ́, ẹ gbọ́dọ̀ pèsè àwọn ohun tara táwọn ọmọ yín nílò. (1 Tím. 5:8) Àmọ́, ẹ rántí pé àjọṣe tó dáa táwọn ọmọ yín ní pẹ̀lú Jèhófà ló máa mú kí wọ́n la ayé búburú yìí já wọnú ayé tuntun, kì í ṣe àwọn nǹkan tara tẹ́ ẹ pèsè fún wọn. (Ìsík. 7:19) Ẹ wo bí inú wa ṣe máa ń dùn tó bá a ṣe ń rí àwọn òbí tó ń ṣe ìpinnu tó mú kí ìdílé wọn túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà! Ohun tí àwọn ọmọ tí wọ́n tọ́ nínú ìdílé bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe nìyẹn táwọn náà bá dàgbà, wọn kì í sì í kábàámọ̀!​—Òwe 10:22. w20.10 28-29 ¶10-11

Sunday, February 20

Èyí ò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ rárá.​—Mát. 16:22.

Àwọn ìgbà kan wà tí àpọ́sítélì Pétérù ṣe àwọn nǹkan tó pa dà kábàámọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ jìyà, kóun sì kú, Pétérù bá a wí, ó sọ ohun tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní fún un. (Mát. 16:21-23) Àmọ́ Jésù tún èrò Pétérù ṣe. Nígbà táwọn jàǹdùkú wá mú Jésù, Pétérù ò tiẹ̀ rò ó lẹ́ẹ̀mejì, ṣe ló gé etí ẹrú àlùfáà àgbà. (Jòh. 18:10, 11) Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jésù tún èrò Pétérù ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, Pétérù tún fọ́nnu pé tí àwọn àpọ́sítélì tó kù bá tiẹ̀ fi Jésù sílẹ̀, òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé. (Mát. 26:33) Nígbà tọ́rọ̀ dójú ẹ̀, ẹ̀rù ba Pétérù tó dára ẹ̀ lójú, ó sì sẹ́ Ọ̀gá ẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹta. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá Pétérù, torí náà, ó “bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.” (Mát. 26:69-75) Ó ṣeé ṣe kó máa ronú pé bóyá ni Jésù máa dárí ji òun. Àmọ́ Pétérù ò jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì yẹn bo òun mọ́lẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Lẹ́yìn tó ṣàṣìṣe, ó kọ́fẹ pa dà, ó sì tún dara pọ̀ mọ́ àwọn àpọ́sítélì yòókù.​—Jòh. 21:1-3; Ìṣe 1:15, 16. w20.12 20 ¶17-18

Monday, February 21

Kí ẹ̀yin ọkọ máa fi òye bá wọn gbé. Ẹ máa bọlá fún wọn bí ohun èlò ẹlẹgẹ́, tó jẹ́ abo.​—1 Pét. 3:7.

Onírúurú ọ̀nà ni olórí ìdílé kan lè gbà fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn. Bí àpẹẹrẹ, kì í retí pé kí ìyàwó tàbí àwọn ọmọ òun máa ṣe nǹkan lọ́nà tó pé tàbí kí wọ́n má ṣàṣìṣe. Ó máa ń fetí sí èrò àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ̀, ó sì máa ń ronú lé e kódà tí èrò wọn bá yàtọ̀ sí tiẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọkọ kan tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń bá ìyàwó rẹ̀ ṣiṣẹ́ ilé, kódà bí àwọn tó wà ládùúgbò bá ka irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sí iṣẹ́ obìnrin. Lóòótọ́ ó lè má rọrùn. Kí nìdí? Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Rachel sọ pé: “Lágbègbè wa, tí ọkọ kan bá ń fọbọ́ tàbí tó ń gbálẹ̀, àwọn ẹbí àtàwọn aládùúgbò máa ń sọ pé obìnrin náà ti sọ ọkọ ẹ̀ di ‘gbẹ̀wù dání,’ wọ́n tiẹ̀ lè máa sọ pé bóyá ìyàwó ẹ̀ ti fún un ní nǹkan jẹ àti pé ó ti di ẹrú ìyàwó ẹ̀.” Tó bá jẹ́ pé irú èrò yìí làwọn èèyàn ní ládùúgbò rẹ, rántí pé Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹrú ló máa ń ṣe iṣẹ́ yìí. Kì í ṣe bí olórí ìdílé kan ṣe máa gbayì lójú ẹbí àti aládùúgbò ló yẹ kó jẹ ẹ́ lọ́kàn, bí kò ṣe bó ṣe máa mú inú ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ dùn. w21.02 2 ¶3; 4 ¶11

Tuesday, February 22

Ohun kan tó dájú ni pé: Bí mo ṣe ń gbàgbé àwọn ohun tí mo fi sílẹ̀ sẹ́yìn, tí mo sì ń nàgà sí àwọn ohun tó wà níwájú, mò ń sapá kí ọwọ́ mi lè tẹ èrè.​—Fílí. 3:​13, 14.

Jèhófà dá wa ká lè máa rántí àwọn nǹkan rere tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn torí pé ìyẹn máa ń múnú wa dùn. Àmọ́ bó ti wù kí nǹkan dáa tó fún wa tẹ́lẹ̀, ayé tuntun máa sàn jù ú lọ fíìfíì. Àwọn èèyàn lè ṣẹ̀ wá, àmọ́ tá a bá dárí jì wọ́n, àá lè pọkàn pọ̀ sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Tá a bá ń dára wa lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ, a ò ní lè fayọ̀ sin Jèhófà. Torí náà, bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ti dárí jì wá. (1 Tím. 1:12-15) Nínú ayé tuntun, a ò ní kú mọ́, àá wà láàyè títí láé, a ò sì ní máa kábàámọ̀ àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Bíbélì sọ nípa ìgbà yẹn pé: “Àwọn ohun àtijọ́ ò ní wá sí ìrántí.” (Àìsá. 65:17) Rò ó wò ná: Àwọn kan lára wa ti dàgbà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àmọ́ nínú ayé tuntun, gbogbo wa máa pa dà di ọ̀dọ́. (Jóòbù 33:25) Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní máa ronú pa dà sẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa wo ayé tuntun lọ́ọ̀ọ́kán, ká sì máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè wà níbẹ̀! w20.11 24 ¶4; 29 ¶18-19

Wednesday, February 23

Mo rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn . . . Wọ́n ń ké jáde pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa . . . àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.”​—Ìfi. 7:​9, 10.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́? Ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ méjì ni Jèhófà máa gbà dá wa nídè nígbà ìpọ́njú ńlá. Àkọ́kọ́, ó máa dá àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ nídè nígbà tó bá mú kí àwọn ọba ayé pa Bábílónì Ńlá run, ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké ayé. (Ìfi. 17:16-18; 18:2, 4) Ìkejì, ó máa dáàbò bo àwa èèyàn ẹ̀ nígbà tó bá pa gbogbo èyí tó kù nínú ayé Sátánì yìí run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 16:14, 16) Tá a bá dúró ti Jèhófà, tá ò sì fi í sílẹ̀, Sátánì ò ní rí wa gbé ṣe. Kódà, Sátánì fúnra ẹ̀ ló máa roko ìgbàgbé. (Róòmù 16:20) Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbé gbogbo ìhámọ́ra ogun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, ká má sì bọ́ ọ sílẹ̀ nígbà kankan! Rántí pé o ò lè dá kojú Sátánì àti ayé èṣù yìí. Torí náà, gbára lé Jèhófà. Máa ti àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lẹ́yìn, kó o sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà Baba wa ọ̀run máa fún ẹ lókun, á sì dáàbò bò ẹ́.​—Àìsá. 41:10. w21.03 30 ¶16-17

Thursday, February 24

Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.​—Àìsá. 30:15.

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa fọkàn balẹ̀, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bó o ṣe ń gbé àwọn ìtàn yìí yẹ̀ wò, kíyè sí ohun tó mú kọ́kàn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń kojú inúnibíni tó le. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn pàṣẹ fáwọn àpọ́sítélì pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, ẹ̀rù ò bà wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fìgboyà sọ fún wọn pé: “A gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.” (Ìṣe 5:29) Kódà lẹ́yìn tí wọ́n nà wọ́n, ọkàn àwọn àpọ́sítélì náà balẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ń ti àwọn lẹ́yìn, inú ẹ̀ sì ń dùn sáwọn. Ìyẹn ló mú kí wọ́n nígboyà láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù lọ. (Ìṣe 5:40-42) Bákan náà, nígbà táwọn alátakò fẹ́ pa Sítéfánù, ọkàn ẹ̀ balẹ̀ débi pé ṣe lojú ẹ̀ “dà bí ojú áńgẹ́lì.” (Ìṣe 6:12-15) Kí nìdí? Ìdí ni pé ó dá a lójú pé òun ti rí ojú rere Jèhófà. w21.01 4 ¶10-11

Friday, February 25

Wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.​—Ìfi. 7:14.

Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, wọ́n sì rí ojúure Jèhófà. (Àìsá. 1:18) Ogunlọ́gọ̀ èèyàn yìí ni àwọn Kristẹni tó yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, tí wọ́n ṣèrìbọmi, tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, tí wọ́n sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Jòh. 3:36; 1 Pét. 3:21) Ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n lè dúró níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì máa ṣe “iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un tọ̀sántòru” lórí ilẹ̀ ayé nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀. (Ìfi. 7:15) Kódà ní báyìí, àwọn ló ń fìtara kópa tó pọ̀ jù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn, wọ́n sì ń fi ire Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú tiwọn. (Mát. 6:33; 24:14; 28:19, 20) Ó dá àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó la ìpọ́njú ńlá náà já lójú pé Ọlọ́run máa bójú tó wọn. Torí Bíbélì sọ pé: “Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ sì máa fi àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n.” Ìlérí tí àwọn àgùntàn mìíràn ti ń retí tipẹ́tipẹ́ máa wá nímùúṣẹ, pé: “[Ọlọ́run] máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.”​—Ìfi. 21:3, 4. w21.01 16 ¶9-10

Saturday, February 26

Èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi sára onírúurú èèyàn, àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò máa sọ tẹ́lẹ̀.​—Ìṣe 2:17.

Inú wa dùn pé a wà nínú ìdílé Jèhófà, gbogbo wa la sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò ipò orí tí Jèhófà ṣe. Bíbélì fi hàn pé bí Jèhófà ṣe mọyì àwọn ọkùnrin náà ló mọyì àwọn obìnrin. Bí àpẹẹrẹ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àtọkùnrin àtobìnrin ni Jèhófà fún ní ẹ̀mí mímọ́, ó sì fún wọn lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, kí wọ́n sì sọ onírúurú èdè. (Ìṣe 2:1-4, 15-18) Bákan náà, tọkùnrin tobìnrin ni Jèhófà fẹ̀mí yàn, tó sì fún wọn láǹfààní láti jọba pẹ̀lú Kristi lọ́run. (Gál. 3:26-29) Yàtọ̀ síyẹn, tọkùnrin tobìnrin ló máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. (Ìfi. 7:9, 10, 13-15) Ìyẹn nìkan kọ́ o, bí Jèhófà ṣe fún àwọn ọkùnrin láǹfààní láti wàásù ìhìn rere kí wọ́n sì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ náà ló fún àwọn obìnrin. (Mát. 28:19, 20) Bí àpẹẹrẹ, ìwé Ìṣe sọ̀rọ̀ nípa arábìnrin kan tó ń jẹ́ Pírísílà tóun àti ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Ákúílà ran ọkùnrin sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan tó ń jẹ́ Àpólò lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ mọ Ìwé Mímọ́ dunjú.​—Ìṣe 18:24-26. w21.02 14 ¶1; 15 ¶4

Sunday, February 27

Ẹ kíyè sí ara yín àti sí gbogbo agbo . . . Ẹ ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run.​—Ìṣe 20:28.

Ẹ̀yin alàgbà, ojúṣe yín ni láti ran àwọn akéde lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. Tójú bá ń ti akéde kan láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níṣojú ẹ, o lè bá a darí ẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ̀yin alàgbà lè ṣe láti fún àwọn akéde níṣìírí kí wọ́n má bàa juwọ́ sílẹ̀. (1 Tẹs. 5:11) Tá ò bá tiẹ̀ ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń darí báyìí, a lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú débi táá fi ṣèrìbọmi. Tá a bá ti múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ dáadáa, àá lè ṣe àwọn àfikún táá gbé akẹ́kọ̀ọ́ náà ró láìsọ̀rọ̀ jù. A lè mú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́rẹ̀ẹ́ tí wọ́n bá wá sípàdé, a sì lè fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn. Bákan náà, àwọn alàgbà lè fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níṣìírí tí wọ́n bá ń fìfẹ́ hàn sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn tí wọ́n bá ń dá àwọn akéde lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì ń gbóríyìn fún wọn, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè máa fayọ̀ bá iṣẹ́ náà nìṣó. Kò sí àní-àní pé gbogbo wa pátá la máa láyọ̀ tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe bó ti wù ó kéré mọ láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ kó lè wá sin Jèhófà Baba wa ọ̀run. w21.03 13 ¶18-19

Monday, February 28

Àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.​—Sm. 25:14.

Ohun tí Dáfídì ṣe fi hàn pé ó ṣeé fọkàn tán, kì í sì í fiṣẹ́ ṣeré. Bí àpẹẹrẹ, àtikékeré ló ti ń bójú tó àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀, àmọ́ iṣẹ́ yìí ò rọrùn rárá. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà lẹ̀mí ẹ̀ máa ń wà nínú ewu. Dáfídì sọ fún Ọba Sọ́ọ̀lù pé: “Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ń ṣọ́ agbo ẹran bàbá rẹ̀, kìnnìún kan wá, lẹ́yìn náà bíárì kan wá pẹ̀lú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì gbé àgùntàn lọ nínú agbo ẹran. Mo gbá tẹ̀ lé e, mo mú un balẹ̀, mo sì gba àgùntàn náà sílẹ̀ lẹ́nu rẹ̀.” (1 Sám. 17:34, 35) Dáfídì mọ̀ pé ojúṣe òun ni láti bójú tó àwọn àgùntàn náà. Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin náà lè fara wé Dáfídì tẹ́ ẹ bá ń rí i dájú pé ẹ ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún yín. Àtikékeré ni Dáfídì ti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Àjọṣe tí Dáfídì ní yìí ṣe pàtàkì ju ìgboyà rẹ̀ àti bó ṣe mọ orin kọ lọ. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run Dáfídì, ó tún jẹ́ Ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, ohun tó ṣe pàtàkì jù tẹ́ ẹ lè ṣe ni pé kẹ́ ẹ jẹ́ kí àjọṣe tẹ́ ẹ ní pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára. w21.03 3 ¶4-5

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́