ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es22 ojú ìwé 26-36
  • March

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • March
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Tuesday, March 1
  • Wednesday, March 2
  • Thursday, March 3
  • Friday, March 4
  • Saturday, March 5
  • Sunday, March 6
  • Monday, March 7
  • Tuesday, March 8
  • Wednesday, March 9
  • Thursday, March 10
  • Friday, March 11
  • Saturday, March 12
  • Sunday, March 13
  • Monday, March 14
  • Tuesday, March 15
  • Wednesday, March 16
  • Thursday, March 17
  • Friday, March 18
  • Saturday, March 19
  • Sunday, March 20
  • Monday, March 21
  • Tuesday, March 22
  • Wednesday, March 23
  • Thursday, March 24
  • Friday, March 25
  • Saturday, March 26
  • Sunday, March 27
  • Monday, March 28
  • Tuesday, March 29
  • Wednesday, March 30
  • Thursday, March 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
es22 ojú ìwé 26-36

March

Tuesday, March 1

Aláyọ̀ ni yín nígbàkigbà tí àwọn èèyàn bá kórìíra yín.​—Lúùkù 6:22.

Kì í wù wá káwọn èèyàn kórìíra wa, inú wa kì í sì í dùn tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa. Torí náà, kí ló máa jẹ́ ká láyọ̀ táwọn èèyàn bá kórìíra wa? Ẹ jẹ́ ká wo ìdí mẹ́ta. Àkọ́kọ́, tá a bá fara dà á, inú Jèhófà máa dùn sí wa. (1 Pét. 4:13, 14) Ìkejì, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára. (1 Pét. 1:7) Ìkẹta, Jèhófà máa fún wa lẹ́bùn iyebíye, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun. (Róòmù 2:6, 7) Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde làwọn àpọ́sítélì bẹ̀rẹ̀ sí í nírú ayọ̀ tí Jésù sọ pé wọ́n máa ní. Lẹ́yìn táwọn aláṣẹ ti nà wọ́n, tí wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, ṣe ni inú wọn ń dùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé “a ti kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ Jésù.” (Ìṣe 5:40-42) Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jésù Ọ̀gá wọn ju ìbẹ̀rù tí wọ́n ní fáwọn ọ̀tá wọn lọ. Wọ́n sì fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọ̀gá wọn bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere náà “láìdábọ̀.” Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń fòótọ́ inú sin Jèhófà nìṣó láìka inúnibíni sí. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ò ní gbàgbé iṣẹ́ tí wọ́n ṣe àti ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn fún orúkọ rẹ̀. w21.03 25 ¶18-19

Wednesday, March 2

Kódà ó ti fi ayérayé sí wọn lọ́kàn.​—Oníw. 3:11.

Kì í ṣe ìgbà tí wọ́n bí Kristẹni kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró ló ti ní ìrètí àtilọ sọ́run. Jèhófà ló fi ìrètí yìí sí wọn lọ́kàn. Wọ́n máa ń ronú nípa ìrètí yìí, wọ́n máa ń gbàdúrà nípa ẹ̀, ara wọn sì máa ń wà lọ́nà láti rí èrè náà gbà. Kódà, wọn ò mọ bí ara wọn ṣe máa rí gan-an nígbà tí wọ́n bá dé ọ̀run. (Fílí. 3:20, 21; 1 Jòh. 3:2) Síbẹ̀, wọ́n ń fojú sọ́nà láti dara pọ̀ mọ́ àwọn yòókù nínú Ìjọba ọ̀run. Àwọn àgùntàn mìíràn ń fojú sọ́nà láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn sì lohun tó ń wu gbogbo èèyàn torí bí Jèhófà ṣe dá wa nìyẹn. Wọ́n ń fojú sọ́nà sí ìgbà tí wọ́n máa sọ gbogbo ayé di Párádísè. Wọ́n ń retí ìgbà tí ara wọn á jí pépé, tí wọ́n á kọ́ ilé ara wọn, tí wọ́n á gbin ọgbà, tí wọ́n á sì bímọ. (Àìsá. 65:21-23) Wọ́n ń retí ìgbà tí wọ́n á lè lọ sí ọ̀pọ̀ ibi láyé, tí wọ́n á rí àwọn òkè ńláńlá, àwọn igbó kìjikìji àti alagbalúgbú omi. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á lè fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ohun tó máa múnú wọn dùn jù ni pé àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà á máa lágbára sí i láti ọjọ́ dé ọjọ́. w21.01 18-19 ¶17-18

Thursday, March 3

Ó sun ilé Ọlọ́run tòótọ́ kanlẹ̀ . . . ó sì ba gbogbo ohun tó ṣeyebíye jẹ́.​—2 Kíró. 36:19.

Lẹ́yìn táwọn ọmọ ogun Bábílónì run ilẹ̀ náà tán, ṣe làwọn èèyàn ń sọ pé: “Ahoro ni, tí kò sí èèyàn àti ẹranko lórí rẹ̀, a sì ti fi í lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà.” (Jer. 32:43) Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méjì (200) lẹ́yìn tí Jóẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, Jèhófà lo wòlíì Jeremáyà láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ míì nípa ìgbéjàkò náà. Ó sọ pé àwọn ará Bábílónì máa fara balẹ̀ wá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń hùwà burúkú kàn, wọ́n á sì mú wọn nígbèkùn. Ó ní: “‘Wò ó, màá ránṣẹ́ pe ọ̀pọ̀ apẹja,’ ni Jèhófà wí, ‘wọ́n á sì mú wọn bí ẹja. Lẹ́yìn ìyẹn, màá ránṣẹ́ pe ọ̀pọ̀ ọdẹ, wọ́n á sì máa dọdẹ wọn kiri lórí gbogbo òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèké àti nínú àwọn pàlàpálá àpáta. . . . Màá san ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó yẹ wọ́n nítorí àṣìṣe wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn.’” Kódà báwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kò ronú pìwà dà yẹn bá sá lọ sísàlẹ̀ alagbalúgbú omi òkun tàbí tí wọ́n fara pa mọ́ sáàárín igbó kìjikìji, ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Bábílónì máa tẹ̀ wọ́n.​—Jer. 16:16, 18. w20.04 5 ¶12-13

Friday, March 4

[Lọ́ọ̀tì] ń lọ́ra ṣáá.​—Jẹ́n. 19:16.

Ìgbà kan wà tó yẹ kí Lọ́ọ̀tì tètè ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe, àmọ́ tó jẹ́ pé ṣe ló ń lọ́ra. Lójú wa, ó lè jọ pé Lọ́ọ̀tì ò ka ọ̀rọ̀ Jèhófà sí tàbí pé aláìgbọràn ni. Àmọ́ Jèhófà ò jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ sú òun. “Torí Jèhófà yọ́nú sí i,” àwọn áńgẹ́lì yẹn fà wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì mú wọn jáde sí ìta ìlú náà. (Jẹ́n. 19:15, 16) Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tí Jèhófà fi gba ti Lọ́ọ̀tì rò. Ó ṣeé ṣe kí Lọ́ọ̀tì máa bẹ̀rù àwọn tó wà ní òde ìlú náà. Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe kó mọ̀ nípa àwọn ọba méjì tó já sínú kòtò tó ní ọ̀dà bítúmẹ́nì nítòsí ìlú wọn. (Jẹ́n. 14:8-12) Ká má sì gbàgbé pé olórí ìdílé ni Lọ́ọ̀tì, torí náà ó lè máa ṣàníyàn nípa ìdílé rẹ̀. Bákan náà, ọlọ́rọ̀ ni, ó sì ṣeé ṣe kó ní ilé tó rẹwà gan-an ní Sódómù. (Jẹ́n. 13:5, 6) Ká sòótọ́, kò yẹ kí Lọ́ọ̀tì torí àwọn ìdí yìí ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Bó ti wù kó rí, Jèhófà gbójú fo àwọn àṣìṣe Lọ́ọ̀tì, ó sì pè é ní “ọkùnrin olódodo.”​—2 Pét. 2:7, 8. w20.04 18 ¶13-14

Saturday, March 5

O ní àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí bí ìrì tó ń sẹ̀.​—Sm. 110:3.

Ṣé ọ̀dọ́ ni ẹ́? Ó lè má rọrùn fáwọn tó mọ̀ ẹ́ nígbà tó o wà ní kékeré láti gbà pé o ti dàgbà báyìí. Àmọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ò fojú ọmọdé wò ẹ́ mọ́. Ó mọ̀ ẹ́, ó sì mọ ohun tó o lè ṣe. (1 Sám. 16:7) Torí náà, ṣe ohun táá jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Dáfídì ṣe ní tiẹ̀? Ṣe ló máa ń wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Ó wá ronú nípa ohun táwọn nǹkan yẹn kọ́ òun nípa Ẹlẹ́dàá. (Sm. 8:3, 4; 139:14; Róòmù 1:20) Ohun míì tó o lè ṣe ni pé kó o bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lókun. Bí àpẹẹrẹ, ṣé àwọn ọmọléèwé rẹ máa ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da ìṣòro yìí. Yàtọ̀ síyẹn, fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run sílò, títí kan àwọn fídíò. Bó o ṣe ń rí i tí Jèhófà ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro kan tẹ̀ lé òmíì, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ rẹ á túbọ̀ máa lágbára. Báwọn míì sì ṣe ń rí i pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà máa mú kí wọ́n fọkàn tán ẹ. w21.03 4 ¶7

Sunday, March 6

Àdúrà àwọn adúróṣinṣin máa ń múnú [Jèhófà] dùn.​—Òwe 15:8.

Àwọn ọ̀rẹ́ tó mọwọ́ ara wọn máa ń bára wọn sọ̀rọ̀, wọ́n sì máa ń finú han ara wọn. Ṣé bí àárín àwa àti Jèhófà náà ṣe rí nìyẹn? Bẹ́ẹ̀ ni! Jèhófà máa ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ibẹ̀ la sì ti mọ èrò rẹ̀ àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀. Àwa náà máa ń bá a sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, kódà a máa ń sọ ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún un. Kì í ṣe pé Jèhófà máa ń tẹ́tí sí àdúrà wa nìkan, ó tún máa ń dáhùn wọn torí pé ọ̀rẹ́ wa ni. Ó máa ń tètè dáhùn àdúrà wa nígbà míì. Ó sì lè gba pé ká gbàdúrà léraléra fún ohun kan náà. Síbẹ̀, ó dá wa lójú pé ó máa dáhùn àdúrà wa lásìkò tó tọ́, ohun tó dáa jù ló sì máa ṣe fún wa. Àmọ́ o, láwọn ìgbà míì ó lè ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ohun tá a gbàdúrà fún. Bí àpẹẹrẹ, dípò kó mú àdánwò kan kúrò, ó lè fún wa lọ́gbọ́n àti okun táá jẹ́ ká “lè fara dà á.” (1 Kọ́r. 10:13) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àǹfààní tó ṣeyebíye tá a ní láti gbàdúrà sí Jèhófà? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà sọ, pé ká “máa gbàdúrà nígbà gbogbo.”​—1 Tẹs. 5:17. w20.05 27-28 ¶7-8

Monday, March 7

Ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.​—Mát. 24:13.

Àwọn tó máa ń kópa nínú eré ọlọ́nà jíjìn máa ń tẹjú mọ́ ọ̀kánkán ibi tí wọ́n ń lọ kí wọ́n má bàa ṣubú. Tó bá tiẹ̀ wá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n ṣubú, ṣe ni wọ́n máa ń dìde tí wọ́n á sì tún máa sáré lọ. Kì í ṣe ohun tó gbé wọn ṣubú ló máa ń gbà wọ́n lọ́kàn bí kò ṣe bí wọ́n ṣe máa sáré náà parí tí wọ́n á sì gba èrè náà. Nínú eré ìje tá à ń sá, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń kọsẹ̀, tá a sì máa ń ṣàṣìṣe lọ́rọ̀ àti níṣe. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn tá a jọ ń sáré ìje náà ló ṣe ohun tó dùn wá. Kò sí kírú ẹ̀ má ṣẹlẹ̀. Aláìpé ni gbogbo wa, bẹ́ẹ̀ la sì jọ wà lójú ọ̀nà tó há èyí tó lọ sí ìyè. Torí náà, kò sí bá ò ṣe ní máa “kọ lu” ara wa tàbí ká ní “ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì” lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Kól. 3:13) Àmọ́ dípò ká máa ronú nípa ohun tẹ́nì kan ṣe sí wa, ẹ jẹ́ ká tẹjú mọ́ èrè tó wà níwájú ká sì máa bá eré ìje náà lọ. Tá a bá bínú tá ò sì sáré mọ́, a ò ní lè parí eré ìje náà, a ò sì ní rí èrè gbà. Yàtọ̀ síyẹn, a lè fa ìdíwọ́ fáwọn míì tó ń gbìyànjú láti sáré lójú ọ̀nà tó há náà. w20.04 26 ¶1; 28 ¶8-9

Tuesday, March 8

Ìjọba yìí . . . máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú, ó máa fòpin sí gbogbo wọn.​—Dán. 2:44.

Wòlíì Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ìjọba tó mú kí nǹkan nira fáwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó fi ère gìrìwò kan tó jẹ́ ti wúrà, fàdákà, bàbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ṣàpèjúwe àwọn ìjọba náà. Ó fi èyí tó gbẹ̀yìn nínú àwọn ìjọba náà wé àtẹ́lẹsẹ̀ ère náà, èyí tó jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀. Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ni àtẹ́lẹsẹ̀ ère náà. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà á ṣì máa ṣàkóso nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa kọ lu gbogbo ìjọba ayé yìí tó sì máa pa wọ́n run. Àpọ́sítélì Jòhánù náà sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ìjọba tó mú kí nǹkan nira fáwọn èèyàn Ọlọ́run. Jòhánù fi àwọn ìjọba yìí wé ẹranko kan tó ní orí méje. Ìkeje lára orí ẹranko náà ṣàpẹẹrẹ Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Èyí bọ́gbọ́n mu torí pé ẹranko náà kò ní ju orí méje lọ. Torí náà, ìkeje lára orí ẹranko náà á ṣì máa ṣàkóso nígbà tí Kristi àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ máa pa ẹranko náà run ráúráú.​—Ìfi. 13:1, 2; 17:13, 14. w20.05 14 ¶11-12

Wednesday, March 9

Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.​—1 Jòh. 4:8.

Ọ̀rọ̀ yìí rán wa létí òtítọ́ pàtàkì kan: Yàtọ̀ sí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìfẹ́ ti wá. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Ìfẹ́ tó ní sí wa yìí ló mú kọ́kàn wa balẹ̀, ká sì láyọ̀. Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn torí pé àṣẹ ni, kì í ṣọ̀rọ̀ bóyá ó wù wá tàbí kò wù wá. (Mát. 22:37-40) Tá a bá mọ Jèhófà dáadáa, kò ní ṣòro fún wa àtipa àṣẹ àkọ́kọ́ mọ́. Ó ṣe tán, ẹni pípé ni Jèhófà, ó ń gba tiwa rò, ó sì ń fìfẹ́ bójú tó wa. Àmọ́ ó lè má rọrùn fún wa láti pa àṣẹ kejì mọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé aláìpé làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, wọ́n sì wà lára àwọn tó sún mọ́ wa jù. Nígbà míì, wọ́n lè sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun kan tó mú ká rò pé wọn ò gba tiwa rò, wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ wa. Jèhófà mọ̀ pé ó lè ṣòro fún wa láti pa àṣẹ kejì yìí mọ́, ìdí nìyẹn tó fi mí sí àwọn kan tó kọ Bíbélì láti sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́. Wọ́n jẹ́ ká mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fìfẹ́ hàn síra wa àti bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn tí Ọlọ́run mí sí yìí ni àpọ́sítélì Jòhánù.​—1 Jòh. 3:11, 12. w21.01 8 ¶1-2

Thursday, March 10

Kí Sátánì má . . . fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n borí wa.​—2 Kọ́r. 2:11.

Yálà a ti pẹ́ nínú òtítọ́ tàbí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí Sátánì má bàa pín ọkàn mi níyà?’ Bí àpẹẹrẹ, bí ètò orí tẹlifíṣọ̀n tàbí àwòrán orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó lè gbé èròkerò wá sí ẹ lọ́kàn bá yọjú, kí lo máa ṣe? Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò burú jù, ó ṣe tán kì í ṣe àwòrán oníhòòhò. Àmọ́ ṣé kì í ṣe pé Sátánì ń wá bó ṣe máa pín ọkàn rẹ níyà? A lè fi ètò orí tẹlifíṣọ̀n tàbí àwòrán orí Íńtánẹ́ẹ̀tì yẹn wé àáké tẹ́nì kan fẹ́ fi la igi ńlá kan. Nígbà tó bá kọ́kọ́ la àáké náà mọ́ igi, ó lè jọ pé igi náà kò ní fọ́ sí wẹ́wẹ́. Àmọ́ tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ léraléra, ó máa la igi náà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ohun tó o rí yẹn ló dà bí ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ fi àáké la igi. Ohun tó dà bíi pé kò léwu níbẹ̀rẹ̀ lè di ohun táá pín ọkàn ẹnì kan níyà táá sì wá mú kó dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà. Torí náà, má ṣe fàyè gba ohunkóhun tó máa mú kó o ro èròkerò! Ṣe ohun táá jẹ́ kí ọkàn rẹ pa pọ̀ kó o lè máa bẹ̀rù Jèhófà. w20.06 11-12 ¶14-15

Friday, March 11

Ó yẹ kí . . .  a . . .  máa ru àìlera àwọn tí kò lókun.​—Róòmù 15:1.

Lẹ́yìn tá a bá ti rí ẹnì kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́, kò yẹ ká pa á tì, ṣe ló yẹ ká ràn án lọ́wọ́ ká sì máa fún un níṣìírí. Ẹni náà lè ní ẹ̀dùn ọkàn bíi ti ọmọ tó filé sílẹ̀ nínú àkàwé Jésù. (Lúùkù 15:17-24) Ohun tójú rẹ̀ sì ti rí nígbà tó wà nínú ayé Sátánì ti lè mú kó di aláìlera nípa tẹ̀mí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa àgùntàn tó sọ nù, ó sọ pé olùṣọ́ àgùntàn náà gbé àgùntàn yẹn lé èjìká rẹ̀, ó sì gbé e pa dà sínú agbo. Lóòótọ́, olùṣọ́ àgùntàn náà ti wá àgùntàn tó sọ nù náà káàkiri, ó sì ṣeé ṣe kó ti rẹ̀ ẹ́. Síbẹ̀, ó rí i pé á dáa kóun gbé àgùntàn náà torí pé kò ní lè dá rìn pa dà sínú agbo. (Lúùkù 15:4, 5) Ó lè gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá ká tó lè ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. Ìdí sì ni pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n láwọn ìṣòro kan tó ń mú kó nira fún wọn láti máa fayọ̀ sin Jèhófà. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Ó ṣe pàtàkì ká gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, ká sì ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Táwọn alàgbà bá ní kó o darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́, ṣé inú ẹ máa dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀? w20.06 28 ¶14-15

Saturday, March 12

Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.​—Jòh. 13:35.

Ó yẹ kí gbogbo wa máa fìfẹ́ hàn torí pé ìyẹn làwọn èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọlẹ́yìn Kristi ni wá lóòótọ́. Àmọ́, ó tún ṣe pàtàkì ká ní “ìmọ̀ tó péye àti òye tó kún rẹ́rẹ́.” (Fílí. 1:9) Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, “gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn àwọn èèyàn” máa ṣì wá lọ́nà títí kan àwọn apẹ̀yìndà. (Éfé. 4:14) Ìgbà kan wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò tẹ̀ lé e mọ́, síbẹ̀ àpọ́sítélì Pétérù fi hàn pé Jésù ló ní “àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 6:67, 68) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ò lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí Jésù sọ, kò fi Jésù sílẹ̀ torí ó fòye mọ̀ pé Jésù ni Kristi. Ìwọ náà lè ṣe ohun táá mú kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ túbọ̀ dá ẹ lójú. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ á dúró digbí lójú àdánwò, wàá sì tún lè ran àwọn míì lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ tiwọn náà lè lágbára.​—2 Jòh. 1, 2. w20.07 8 ¶2; 13 ¶18

Sunday, March 13

Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, kò yẹ kí ìfẹ́ wa jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí ti ahọ́n, àmọ́ ó yẹ kó jẹ́ ní ìṣe àti òtítọ́.​—1 Jòh. 3:18.

Tá a bá fẹ́ káwọn ará wa máa rìn nínú òtítọ́, a gbọ́dọ̀ máa fi àánú hàn sí wọn. (1 Jòh. 3:10, 11, 16, 17) Kì í ṣe ìgbà tí nǹkan bá ń lọ dáadáa nìkan la fẹ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, a tún fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá níṣòro. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o mọ ẹnì kan téèyàn rẹ̀ kú tó sì nílò ìtùnú? Ṣé o mọ ẹnì kan tó níṣòro tó sì nílò ìrànlọ́wọ́? Àbí ṣé o gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa tíyẹn mú kí wọ́n pàdánù ohun ìní wọn, tí wọ́n sì wá nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ilé míì? Kì í ṣe ohun tá a bá sọ nírú àkókò yìí nìkan ló máa tu àwọn ará wa nínú, a tún gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́.Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn míì, Jèhófà là ń fara wé yẹn. (1 Jòh. 4:7, 8) Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fìfẹ́ hàn ni pé ká máa dárí ji ara wa. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tó ṣẹ̀ wá lè bẹ̀ wá pé ká má bínú. Tá a bá fẹ́ fìfẹ́ hàn lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ dárí jì í, kọ́rọ̀ náà sì tán nínú wa.​—Kól. 3:13. w20.07 24 ¶14-15

Monday, March 14

Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.​—Ìṣe 24:15.

Ṣé a máa kọ́ àwọn tó jíǹde lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lónìí? Ṣé wọ́n máa yàn wọ́n sí ìjọ táwọn náà á sì wá máa kọ́ àwọn míì tó jíǹde lẹ́yìn wọn? Àfi ká dúró dìgbà yẹn. Àmọ́ ohun kan wà tó dá wa lójú, nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá máa fi parí, “ìmọ̀ Jèhófà [ti] máa bo ayé.” (Àìsá. 11:9) Ó dájú pé ọwọ́ wa máa dí gan-an, inú wa sì máa dùn nígbà ẹgbẹ̀rún ọdún yẹn! Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà láyé la máa ṣe àwọn àtúnṣe táá jẹ́ ká múnú Jèhófà dùn nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Torí náà, ó di dandan ká gba tàwọn tó ṣẹ̀sẹ̀ jíǹde rò bí wọ́n ṣe ń sapá láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọn tí wọ́n sì ń fi ìlànà Jèhófà sílò. (1 Pét. 3:8) Kò sí àní-àní pé àwọn tó jíǹde yẹn máa nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn Jèhófà tá à ń fìrẹ̀lẹ̀ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ báwa náà ṣe ń “ṣiṣẹ́ ìgbàlà [wa] yọrí.”​—Fílí. 2:12. w20.08 16 ¶6-7

Tuesday, March 15

Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò, . . . kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.​—Gál. 6:4.

Tá a bá fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sílò, tá a sì ń kíyè sí àwọn ohun tá a lè ṣe, àá rí i pé àwa náà ní ẹ̀bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, alàgbà kan lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́ lórí pèpéle, àmọ́ kó mọ béèyàn ṣe ń wàásù dáadáa kó sì sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ bá a ṣe ń ṣètò nǹkan bíi tàwọn alàgbà míì, àmọ́ ó máa ń yá àwọn akéde lára láti lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé ìmọ̀ràn Bíbélì ló máa fún àwọn. Ó sì lè jẹ́ ẹni táwọn èèyàn mọ̀ pé ó máa ń ṣàlejò gan-an. (Héb. 13:2, 16) Tá a bá mọyì ẹ̀bùn tá a ní àtohun tá a lè ṣe, ọkàn wa á balẹ̀ pé àwa náà wúlò nínú ìjọ. A ò sì ní máa jowú àwọn ará tó lẹ́bùn táwa ò ní. Ẹ̀bùn yòówù ká ní tàbí ohun yòówù ká lè ṣe, gbogbo wa ló yẹ ká máa sapá láti sunwọ̀n sí i. w20.08 24 ¶16-18

Wednesday, March 16

Mo rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn, tí èèyàn kankan kò lè ka iye wọn.​—Ìfi. 7:9.

Arákùnrin J. F. Rutherford sọ àsọyé mánigbàgbé kan tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Ogunlọ́gọ̀ Ńlá” lọ́dún 1935, ní àpéjọ kan tí wọ́n ṣe ní Washington, D.C., lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nínú àsọyé tí Arákùnrin Rutherford sọ, ó ṣàlàyé àwọn tó jẹ́ “ọ̀pọlọpọ enia” (Bíbélì Mímọ́) tàbí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó wà nínú Ìfihàn 7:9. Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà pé “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” náà máa lọ sí ọ̀run bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ nígbàgbọ́ bíi ti àwọn ẹni àmì òróró. Arákùnrin Rutherford fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé pé “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” náà kò ní lọ sọ́run. Àmọ́ wọ́n jẹ́ ara àwọn àgùntàn mìíràn ti Kristi, tó máa la “ìpọ́njú ńlá náà” já, tí wọ́n á sì gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (Ìfi. 7:14) Jésù ṣèlérí pé: “Mo ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kò sí lára ọ̀wọ́ yìí; mo gbọ́dọ̀ mú àwọn yẹn náà wá, wọ́n á fetí sí ohùn mi, wọ́n á sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.” (Jòh. 10:16) Àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà làwọn àgùntàn mìíràn yìí, wọ́n sì nírètí àtiwà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.​—Mát. 25:31-33, 46. w21.01 14 ¶1-2

Thursday, March 17

Gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi, ṣùgbọ́n ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.​—Mát. 10:22.

A gbọ́dọ̀ máa kó ara wa níjàánu tá a bá máa fara dà á ká sì ṣiṣẹ́ ìwàásù náà parí. (Mát. 28:19, 20) Wọn kì í bí ìkóra-ẹni-níjàánu mọ́ni. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó bá rọ àwa èèyàn lọ́rùn la sábà máa ń ṣe. Torí náà, ó gba ìsapá gan-an kéèyàn tó lè kó ara ẹ̀ níjàánu, kó sì ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, a nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ká lè ṣe ohun tó ṣòro fún wa láti ṣe. Jèhófà sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Gál. 5:22, 23) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń kó ara ẹ̀ níjàánu gan-an. Kódà, ó sọ pé òun máa “ń lu ara [òun] kíkankíkan” kóun bàa lè ṣe ohun tó tọ́. (1 Kọ́r. 9:25-27) Ó gba àwọn míì níyànjú pé kí wọ́n máa kó ara wọn níjàánu kí wọ́n sì máa ṣe ohun gbogbo “lọ́nà tó bójú mu àti létòlétò.” (1 Kọ́r. 14:40) Ó gba ìsapá àti ìkóra-ẹni-níjàánu ká tó lè máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó ká sì máa wàásù déédéé.​—Ìṣe 2:46. w20.09 6-7 ¶15-17

Friday, March 18

A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.​—Máàkù 13:10.

Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè la ti ń wàásù láìsí ìdíwọ́ lónìí. Ṣé bó ṣe rí lórílẹ̀-èdè tó ò ń gbé nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó o bi ara ẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe ń lo àsìkò tí àlàáfíà wà yìí?’ Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí onírúurú nǹkan ń ṣẹlẹ̀ yìí, àwa èèyàn Jèhófà ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni ju ti ìgbàkigbà rí lọ nínú ìtàn. Ọ̀pọ̀ nǹkan la sì lè ṣe nínú iṣẹ́ náà. Báwo lo ṣe lè fọgbọ́n lo àkókò tí àlàáfíà wà yìí? (2 Tím. 4:2) O ò ṣe wò ó bóyá ìwọ tàbí ẹnì kan nínú ìdílé yín lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bóyá kẹ́ ẹ tiẹ̀ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Kì í ṣe àsìkò yìí ló yẹ ká máa kó nǹkan tara jọ, ó ṣe tán àwọn nǹkan yẹn ò ní bá wa la ìpọ́njú ńlá já. (Òwe 11:4; Mát. 6:31-33; 1 Jòh. 2:15-17) Ọ̀pọ̀ lára wa ló ti kọ́ èdè tuntun kí wọ́n lè túbọ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Kó lè rọrùn fún wọn láti wàásù fún àwọn tó ń sọ onírúurú èdè, ètò Jèhófà ti ṣe àwọn ìtẹ̀jáde láwọn èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000)! w20.09 16 ¶9-11

Saturday, March 19

Máa . . . ja ogun rere.​—1 Tím. 1:18.

Ọmọ ogun tó dáa máa ń jẹ́ adúróṣinṣin. Gbogbo ohun tó bá gbà ló máa ṣe kó lè dáàbò bo ẹni tó fẹ́ràn tàbí ohun tó ṣe pàtàkì sí i. Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé kó ní ìfọkànsin Ọlọ́run, ìyẹn ni pé kó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, kó má sì yẹsẹ̀. (1 Tím. 4:7) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà jinlẹ̀, tá a sì ń fi gbogbo ọkàn wa sìn ín, a máa fọwọ́ gidi mú òtítọ́, a ò sì ní jẹ́ kó bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. (1 Tím. 4:8-10; 6:6) Ọmọ ogun kan gbọ́dọ̀ máa kó ara ẹ̀ níjàánu tó bá ṣì fẹ́ máa ja ogun nìṣó. Ohun tó jẹ́ kí Tímótì lè máa ja ogun tẹ̀mí nìṣó ni pé ó fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò pé kó sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, kó ní àwọn ànímọ́ tó dáa, kó sì máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀. (2 Tím. 2:22) Ìyẹn gba pé kí Tímótì máa kó ara ẹ̀ níjàánu. Táwa náà bá máa borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ó ṣe pàtàkì ká máa kó ara wa níjàánu. (Róòmù 7:21-25) Yàtọ̀ síyẹn, a nílò ìkóra-ẹni-níjàánu tá a bá máa bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ ká sì gbé ìwà tuntun wọ̀. (Éfé. 4:22, 24) Bákan náà, ó gba ìkóra-ẹni-níjàánu ká tó lè lọ sípàdé lẹ́yìn tá a ti ibi iṣẹ́ dé tó sì ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu.​—Héb. 10:24, 25. w20.09 28 ¶9-11

Sunday, March 20

Mo ti pinnu láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ nígbà gbogbo, màá sì ṣe bẹ́ẹ̀ délẹ̀délẹ̀.​—Sm. 119:112.

Ó yẹ ká mú sùúrù bá a ṣe ń ran akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú títí táá fi yara ẹ̀ sí mímọ́ táá sì ṣèrìbọmi. Àmọ́ ó tún yẹ ká mọ̀ bóyá ó fẹ́ sin Jèhófà lóòótọ́. Ǹjẹ́ o rí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó ń pa àṣẹ Jésù mọ́? Àbí ṣe ló kàn fẹ́ ní ìmọ̀ Bíbélì? Máa fiyè sí àwọn ohun tó fi hàn pé akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ń tẹ̀ síwájú. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ó máa ń sọ bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó? Ṣé ó máa ń gbàdúrà sí Jèhófà? (Sm. 116:1, 2) Ṣé ó máa ń ka Bíbélì déédéé? (Sm. 119:97) Ṣé ó máa ń wá sípàdé déédéé? (Sm. 22:22) Ṣé ó ti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ? Ṣé ó ti ń sọ àwọn nǹkan tó ń kọ́ fún tẹbítọ̀rẹ́? (Sm. 9:1) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ṣé ó wù ú láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (Sm. 40:8) Tí akẹ́kọ̀ọ́ náà kò bá tíì ṣe èyíkéyìí nínú ohun tá a sọ yìí, bá a sọ ọ́ tìfẹ́tìfẹ́, síbẹ̀ rí i pé o sọ ojú abẹ níkòó. w20.10 18 ¶14-15

Monday, March 21

Ẹni tó rán mi wà pẹ̀lú mi; kò pa mí tì lémi nìkan, torí gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣe ohun tó wù ú.​—Jòh. 8:29.

Ìgbà gbogbo ni Jèhófà Baba Jésù máa ń ṣèpinnu tó tọ́, àwọn òbí tó tọ́ ọ dàgbà náà sì máa ń ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Àmọ́ bí Jésù ṣe ń dàgbà, ó di dandan kóun náà ṣèpinnu fúnra ẹ̀. (Gál. 6:5) Torí pé èèyàn bíi tiwa ni, òun náà ní òmìnira láti yan ohun tó fẹ́. Ó lè pinnu pé ohun tó wu òun ni òun máa ṣe láìfi ti Jèhófà pè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ lòun máa ṣe. Nígbà tí Jésù mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe, ó pinnu pé ohun tí òun máa ṣe nìyẹn. (Jòh. 6:38) Ó mọ̀ pé àwọn èèyàn máa kórìíra òun, ìyẹn sì lè má rọrùn fún un. Síbẹ̀, ó pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ lòun máa ṣe. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi ní 29 S.K., ohun tó ṣe pàtàkì sí i jù ni bó ṣe máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà. (Héb. 10:5-7) Kódà nígbà tó ń kú lọ lórí òpó igi oró, kò bọ́hùn.​—Jòh. 19:30. w20.10 29 ¶12; 30 ¶15

Tuesday, March 22

Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.​—Héb. 13:5.

Ǹjẹ́ o mọ arákùnrin tàbí arábìnrin èyíkéyìí nínú ìjọ yín tó ń ṣàìsàn tàbí tó ní àwọn ìṣòro míì tàbí téèyàn ẹ̀ kú? Tó o bá mọ irú ẹni bẹ́ẹ̀, o ò ṣe bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè sọ ọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun kan tó máa tù ú nínú. Ó lè jẹ́ ohun tó o sọ tàbí ohun tó o ṣe yẹn ló máa fún ẹni náà lókun lásìkò yẹn. (1 Pét. 4:10) Ọkàn wa balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa. Jèhófà máa ń lo Jésù àtàwọn áńgẹ́lì láti ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tó bá sì bá ìfẹ́ ẹ̀ mu, ó lè lo àwọn tó wà nípò àṣẹ láti ràn wá lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ wa la ti rí bí Jèhófà ṣe lo ẹ̀mí ẹ̀ láti mú kí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Torí náà, bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àwa náà lè fi gbogbo ẹnu sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?”​—Héb. 13:6. w20.11 17 ¶19-20

Wednesday, March 23

Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.​—Àìsá. 30:15.

Ó dá àwọn àpọ́sítélì lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn. Ó ṣe tán, ó fún wọn lágbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu. (Ìṣe 5:12-16; 6:8) Àmọ́, àwa ò lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu lónìí. Síbẹ̀, Jèhófà lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti mú un dá wa lójú pé tá a bá ń jìyà nítorí òdodo, a máa rí ojú rere òun, òun á sì fún wa ní ẹ̀mí mímọ́. (1 Pét. 3:14; 4:14) Torí náà, dípò ká máa ronú ṣáá nípa ohun tá a máa ṣe tí wọ́n bá ṣenúnibíni sí wa lọ́jọ́ iwájú, ṣe ló yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nísinsìnyí kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa tì wá lẹ́yìn, á sì gbà wá là. Àwa náà gbọ́dọ̀ fi ìlérí Jésù sọ́kàn pé: “Màá fún yín ní àwọn ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n tí gbogbo àwọn alátakò yín lápapọ̀ ò ní lè ta kò tàbí kí wọ́n jiyàn rẹ̀.” Jésù tún jẹ́ kó dá wa lójú pé: “Tí ẹ bá ní ìfaradà, ẹ máa lè pa ẹ̀mí yín mọ́.” (Lúùkù 21:12-19) Ká má sì gbàgbé pé Jèhófà rántí kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́. Tí wọ́n bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí wọn dìde. w21.01 4 ¶12

Thursday, March 24

Mo ní ìrètí nínú Ọlọ́run . . . pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.​—Ìṣe 24:15.

Kì í ṣe Pọ́ọ̀lù lẹni àkọ́kọ́ tó gbà pé àjíǹde máa wà, Jóòbù náà gbà bẹ́ẹ̀. Ó dá a lójú pé Ọlọ́run máa rántí òun, á sì jí òun dìde. (Jóòbù 14:7-10, 12-15) “Àjíǹde àwọn òkú” wà lára “ìpìlẹ̀” tàbí “àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀” àwa Kristẹni. (Héb. 6:1, 2) Inú Kọ́ríńtì Kìíní orí 15 ni ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa àjíǹde wà. Ó sì dájú pé ohun tó sọ máa fún àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní níṣìírí. Bákan náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí máa fún àwa náà níṣìírí á sì jẹ́ kí ìrètí yìí túbọ̀ dá wa lójú bó ti wù ká pẹ́ tó nínú ètò Ọlọ́run. Àjíǹde Jésù ló mú kó dá wa lójú pé àwọn èèyàn wa tó ti kú máa jíǹde. Àjíǹde Jésù wà lára “ìhìn rere” tí Pọ́ọ̀lù kéde fáwọn ará Kọ́ríńtì. (1 Kọ́r. 15:1, 2) Kódà, ó sọ pé tí Kristẹni kan ò bá gbà pé Jésù jíǹde, ìgbàgbọ́ rẹ̀ ò wúlò.​—1 Kọ́r. 15:17. w20.12 2 ¶2-4

Friday, March 25

Pétérù wá rántí ohun tí Jésù sọ . . . Ló bá bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.​—Mát. 26:75.

Kí ló jẹ́ kí àpọ́sítélì Pétérù kọ́fẹ pa dà? Ohun kan ni pé ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù ti gbàdúrà fún Pétérù kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ má bàa yẹ̀. Jèhófà dáhùn àdúrà àtọkànwá yẹn. Nígbà tó yá, Jésù fara han Pétérù lóun nìkan kó lè fún un lókun. (Lúùkù 22:32; 24:33, 34; 1 Kọ́r. 15:5) Lóru ọjọ́ kan táwọn àpọ́sítélì ń wá ẹja títí àmọ́ tí wọn ò rẹ́ja pa, Jésù fara hàn wọ́n. Nígbà tó ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ yẹn, Jésù fún Pétérù láǹfààní láti fi hàn bóyá ó nífẹ̀ẹ́ òun. Ó ṣe kedere pé Jésù ti dárí ji ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n yìí, ó sì fún un ní iṣẹ́ míì láti ṣe. (Jòh. 21:15-17) Ohun tí Jésù ṣe fún Pétérù fi hàn pé aláàánú ni Jésù, Jèhófà ló sì fìyẹn jọ. Torí náà tá a bá ṣàṣìṣe, ká má ṣe ronú pé Jèhófà ò lè dárí jì wá láé. Ká rántí pé ohun tí Sátánì fẹ́ ká máa rò gan-an nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wò wá, ká rántí pé aláàánú ni, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa. Irú ojú yìí kan náà ló yẹ ká fi máa wo àwọn tó bá ṣẹ̀ wá.​—Sm. 103:13, 14. w20.12 20-21 ¶17-19

Saturday, March 26

Mi ò ní mikàn.​—Sm. 27:3.

A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tí kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Tá a bá gbé àwọn àpẹẹrẹ wọn yẹ̀ wò, kò ní jẹ́ ká ṣe irú àṣìṣe tí wọ́n ṣe. Ó ṣe tán àwọn èèyàn máa ń sọ pé, àgbà tó jìn sí kòtò, ó kọ́ ará yòókù lọ́gbọ́n. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ásà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, Jèhófà ló máa ń ké pè tó bá ti níṣòro. Àmọ́ nígbà tó yá, kò wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà mọ́, dípò bẹ́ẹ̀ ó máa ń fẹ́ dá yanjú ìṣòro ara ẹ̀. (2 Kíró. 16:1-3, 12) Lójú èèyàn, ó lè jọ pé bí Ásà ṣe lọ bẹ àwọn ará Síríà lọ́wẹ̀ yẹn bọ́gbọ́n mu. Àmọ́ àlàáfíà tí wọ́n ní ò tọ́jọ́. Jèhófà wá tipasẹ̀ wòlíì kan sọ fún un pé: “Nítorí o gbẹ́kẹ̀ lé ọba Síríà, tí o kò sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rẹ, àwọn ọmọ ogun ọba Síríà ti bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́.” (2 Kíró. 16:7) Tá a bá níṣòro, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ máa gbára lé òye tara wa, kàkà bẹ́ẹ̀ ó yẹ ká jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kódà tí nǹkan kan bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ tó sì gba pé ká ṣèpinnu ní pàjáwìrì, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ ká sì gbára lé Jèhófà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ ká ṣèpinnu tó tọ́. w21.01 6 ¶13-15

Sunday, March 27

Ebi ò ní pa wọ́n mọ́.​—Ìfi. 7:16.

Ní báyìí, ebi ń pa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan nítorí ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ tàbí nítorí ogun. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti ju àwọn míì sẹ́wọ̀n nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Àmọ́, inú àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn ń dùn torí wọ́n mọ̀ pé lẹ́yìn tí Jèhófà bá pa ayé èṣù yìí run, ebi ò ní pa àwọn mọ́ nípa tẹ̀mí àti nípa tara torí ọ̀pọ̀ oúnjẹ ló máa wà. Nígbà tí Jèhófà bá pa ayé èṣù yìí run, ó máa dáàbò bo àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn, kò sì ní jẹ́ kí ‘ooru tó ń jóni’ gbẹ tó dà sórí àwọn orílẹ̀-èdè kàn wọ́n. Lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá parí, Jésù máa darí àwọn tó là á já lọ síbi “àwọn ìsun omi ìyè” àìnípẹ̀kun. (Ìfi. 7:17) Rò ó wò ná: Ìrètí àgbàyanu ló ń dúró de àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé nínú gbogbo àwọn tó gbé láyé, àwọn nìkan ni ò ní tọ́ ikú wò, wọ́n sì lè má kú láé! (Jòh. 11:26) Ìrètí àgbàyanu tí àwọn àgùntàn mìíràn ní mú kí wọ́n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti Jésù nígbà gbogbo. w21.01 16-17 ¶11-12

Monday, March 28

Olóòótọ́ ni Olúwa, yóò fún yín lókun, yóò sì dáàbò bò yín.​—2 Tẹs. 3:3.

Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù ronú nípa ìṣòro táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ní. Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó gbàdúrà pé kí Jèhófà “máa ṣọ́ wọn torí ẹni burúkú náà.” (Jòh. 17:14, 15) Jésù mọ̀ pé lẹ́yìn tóun bá pa dà sọ́run, Sátánì Èṣù á máa gbógun ti àwọn tó bá fẹ́ sin Jèhófà. Kò sí àní-àní pé wọ́n á nílò ààbò Jèhófà. Àsìkò wa yìí gan-an la nílò ààbò Jèhófà jù. Ìdí ni pé wọ́n ti lé Sátánì kúrò lọ́run, ó sì “ń bínú gidigidi.” (Ìfi. 12:12) Ó ti mú káwọn kan gbà pé táwọn bá ń ṣenúnibíni sí wa, “iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run” làwọn ń ṣe. (Jòh. 16:2) Àwọn míì tí ò sì gba Ọlọ́run gbọ́ ń ṣe inúnibíni sí wa torí pé a kì í ṣe bíi tiwọn. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ọkàn wa balẹ̀. Kí nìdí? A rí ìdáhùn nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. w21.03 26 ¶1, 3

Tuesday, March 29

[Kò sóhun tó] máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.​—Róòmù 8:39.

Ìfẹ́ ló ń mú kí Jèhófà ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó ń pèsè àwọn nǹkan tá a nílò. Ìfẹ́ tó ní ló mú kó pèsè ìràpadà fún wa. Jésù náà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an débi pé ó fẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ fún wa. (Jòh. 3:16; 15:13) Kò sí ohunkóhun tó lè mú kí Jèhófà àti Jésù má nífẹ̀ẹ́ àwọn tó jẹ́ olóòótọ́. (Jòh. 13:1; Róòmù 8:35) Lọ́nà kan náà, ìfẹ́ ló yẹ kó máa mú olórí ìdílé kan ṣe gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Kí nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin [tàbí ìdílé] rẹ̀ tó rí, kò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí kò rí.” (1 Jòh. 4:11, 20) Ọkùnrin tó nífẹ̀ẹ́ ìdílé rẹ̀ máa fara wé Jèhófà àti Jésù, á máa pèsè fún wọn nípa tara àti nípa tẹ̀mí, á sì máa ṣe ohun táá fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. (1 Tím. 5:8) Yàtọ̀ síyẹn, á máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, á sì máa bá wọn wí. Bákan náà, á máa ṣe ìpinnu táá mú inú Jèhófà dùn táá sì ṣe ìdílé ẹ̀ láǹfààní. w21.02 5 ¶12-13

Wednesday, March 30

Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì gbé ọ ró.​—Sm. 55:22.

Baba wa ọ̀run mọ ohun tí ojú wa ti rí sẹ́yìn, ó sì mọ báwọn nǹkan yẹn ṣe máa ń bà wá nínú jẹ́. Bákan náà, Baba wa ọ̀run máa ń rí ibi tí a dáa sí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè máa ṣe wá bíi pé a ò wúlò. (1 Jòh. 3:19, 20) Ẹnì kan tó ti ń sapá láti borí kùdìẹ̀-kudiẹ kan lè tún ṣe àṣìṣe kan náà, ìyẹn sì lè mú kó rẹ̀wẹ̀sì. Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tírú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ sí tínú ẹ̀ ò ní bà jẹ́. (2 Kọ́r. 7:10) Àmọ́, kò yẹ ká ro ara wa pin ká wá máa ronú pé: ‘Mi ò wúlò rárá. Bóyá ni Jèhófà á lè dárí jì mí.’ Irú èrò yìí ò tọ̀nà rárá, tá ò bá sì ṣọ́ra, ó lè mú ká fi Jèhófà sílẹ̀. Dípò tá a fi máa ro ara wa pin, ṣe ló yẹ ká gbàdúrà sí Jèhófà, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣàánú wa kí àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ lè pa dà gún régé. (Àìsá. 1:18) Tí Jèhófà bá rí i pé o ronú pìwà dà tọkàntọkàn, á dárí jì ẹ́. Láfikún sí i, tọ àwọn alàgbà lọ, wọ́n á fìfẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè kọ́fẹ pa dà nípa tẹ̀mí.​—Jém. 5:14, 15. w20.12 23 ¶5-6

Thursday, March 31

[Mú] àwọn àgbà obìnrin bí ìyá, àwọn ọ̀dọ́bìnrin bí ọmọ ìyá.​—1 Tím. 5:2.

Jésù máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin, ó sì máa ń pọ́n wọn lé. Kò ṣe bíi tàwọn Farisí tí wọ́n máa ń fojú burúkú wo àwọn obìnrin, kódà wọn kì í bá wọn sọ̀rọ̀ ní gbangba, ká má tíì sọ pé wọ́n á kọ́ wọn ní Ìwé Mímọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, Jésù máa ń kọ́ àwọn obìnrin láwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣe pàtàkì bó ṣe ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yòókù. (Lúùkù 10:38, 39, 42) Bákan náà, àwọn obìnrin wà lára àwọn tí wọ́n jọ ń wàásù láti ìlú kan dé ibòmíì. (Lúùkù 8:1-3) Kódà, àwọn obìnrin ni Jésù rán pé kí wọ́n lọ sọ fún àwọn àpọ́sítélì pé òun ti jíǹde. (Jòh. 20:16-18) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dìídì sọ fún Tímótì pé kó máa bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin. Pọ́ọ̀lù gbà pé ìyá Tímótì àti ìyá rẹ̀ àgbà ló kọ́kọ́ gbin ẹ̀kọ́ òtítọ́ sọ́kàn rẹ̀. (2 Tím. 1:5; 3:14, 15) Bákan náà, Pọ́ọ̀lù dìídì dárúkọ àwọn arábìnrin tó fẹ́ kí wọ́n bá òun kí nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ní Róòmù. Kì í ṣe pé ó mọyì iṣẹ́ táwọn arábìnrin yẹn ṣe nìkan, ó tún gbóríyìn fún wọn.​—Róòmù 16:1-4, 6, 12; Fílí. 4:3. w21.02 15 ¶5-6

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́