ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es22 ojú ìwé 37-46
  • April

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • April
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Friday, April 1
  • Saturday, April 2
  • Sunday, April 3
  • Monday, April 4
  • Tuesday, April 5
  • Wednesday, April 6
  • Thursday, April 7
  • Friday, April 8
  • Saturday, April 9
  • Sunday, April 10
  • Monday, April 11
  • Tuesday, April 12
  • Wednesday, April 13
  • Thursday, April 14
  • ỌJỌ́ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
    Lẹ́yìn Tí Oòrùn Bá Wọ̀
    Friday, April 15
  • Saturday, April 16
  • Sunday, April 17
  • Monday, April 18
  • Tuesday, April 19
  • Wednesday, April 20
  • Thursday, April 21
  • Friday, April 22
  • Saturday, April 23
  • Sunday, April 24
  • Monday, April 25
  • Tuesday, April 26
  • Wednesday, April 27
  • Thursday, April 28
  • Friday, April 29
  • Saturday, April 30
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
es22 ojú ìwé 37-46

April

Friday, April 1

Gbogbo ohun tí a kọ ní ìṣáájú ni a kọ fún wa láti gba ẹ̀kọ́.​—Róòmù 15:4.

Ṣé àwọn ìṣòro kan wà tó ń bá ẹ fínra báyìí? Ṣé ẹnì kan nínú ìjọ ló ṣe ohun tó dùn ẹ́? (Jém. 3:2) Bóyá ẹnì kan níbi iṣẹ́ rẹ tàbí ọmọ ilé ìwé rẹ kan ló ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé ò ń sin Jèhófà. (1 Pét. 4:3, 4) Ó sì lè jẹ́ pé àwọn ará ilé ẹ ló ń fúngun mọ́ ẹ pé kó o má lọ sípàdé mọ́, kó o má sì wàásù mọ́. (Mát. 10:35, 36) Bí ìṣòro náà bá dójú ẹ̀ tán, ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìṣòro yòówù kó máa bá ẹ fínra, Jèhófà máa fún ẹ ní ọgbọ́n àti okun táá jẹ́ kó o lè fara dà á. Jèhófà rí i dájú pé àpẹẹrẹ àwọn tó fara da ìṣòro wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà fẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ ohun tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní. Torí náà, tá a bá ń ka irú àwọn àkọsílẹ̀ yìí, á tù wá nínú, á sì jẹ́ ká nírètí. Àmọ́ o, kì í ṣe ká kàn máa ka Bíbélì, tá a bá máa jàǹfààní, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohun tá à ń kà wọ̀ wá lọ́kàn, kó sì yí èrò wa pa dà. w21.03 14 ¶1-2

Saturday, April 2

Ẹ . . . wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun, wọ́n ti tó kórè.​—Jòh. 4:35.

Ṣé ò ń wo àwọn tó ò ń wàásù fún bí ọkà tó ti tó kórè? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tó o gbọ́dọ̀ ṣe. Àkọ́kọ́, ó yẹ kó o fi kún ìtara tó o fi ń wàásù. Àkókò ìkórè ti dín kù, kò sì yẹ ká fàkókò ṣòfò. Ìkejì, ó yẹ kí inú rẹ máa dùn bó o ṣe ń rí i táwọn èèyàn ń tẹ́tí sí ìhìn rere, ó ṣe tán Bíbélì sọ pé: ‘Àwọn èèyàn ń yọ̀ nígbà ìkórè.’ (Àìsá. 9:3) Ìkẹta, máa fi sọ́kàn pé kò sẹ́ni tí kò lè di ọmọ ẹ̀yìn, ìyẹn á sì mú kó o máa yí bó o ṣe ń bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀ pa dà. Jésù kò fojú táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi wo àwọn ará Samáríà wò wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà pé wọ́n lè yí pa dà kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó yẹ káwa náà gbà pé àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Àpẹẹrẹ àtàtà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ fún wa tó bá dọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù. Ó mọ ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́, ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, ó sì gbà pé wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn. w20.04 8-9 ¶3-4

Sunday, April 3

Isà Òkú àti ibi ìparun ṣí sílẹ̀ gbayawu lójú Jèhófà. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ọkàn èèyàn!​—Òwe 15:11.

Dípò tá a fi máa ṣàríwísí àwọn èèyàn, ṣe ló yẹ ká gbìyànjú láti mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Jèhófà nìkan ló mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa gan-an. Torí náà, bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kó o máa rí ohun tó ń rí lára àwọn èèyàn, kó o sì ní kó jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè máa gba tiwọn rò. Gbogbo àwọn ará wa ló yẹ ká máa gba tiwọn rò, ká má ṣe ya ẹnikẹ́ni sọ́tọ̀. Gbogbo wọn ló ń kojú ìṣòro bíi ti Jónà, Èlíjà, Hágárì àti Lọ́ọ̀tì. Díẹ̀ lára àwọn ìṣòro náà sì lè jẹ́ èyí tí wọ́n fọwọ́ ara wọn fà. Ká sòótọ́, ṣé a rẹ́ni tó lè sọ pé irú ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ sóun rí? Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé Jèhófà ní ká máa gba ti ara wa rò. (1 Pét. 3:8) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa pa kún ìṣọ̀kan tó wà láàárín ẹgbẹ́ ará kárí ayé. Torí náà, pinnu pé wàá máa fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn ará, wàá túbọ̀ mọ̀ wọ́n, wàá sì máa gba tiwọn rò. w20.04 18-19 ¶15-17

Monday, April 4

Kristi jìyà torí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín kí ẹ lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.​—1 Pét. 2:21.

Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́. Torí náà, ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣègbọràn sí Jèhófà ni pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù pẹ́kípẹ́kí bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Jòh. 8:29) Tá a bá fẹ́ máa bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́, ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà ni Ọlọ́run òtítọ́ àti pé òtítọ́ ni gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó tún gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Lónìí, ọ̀pọ̀ ni ò gbà pé Jésù Ọba tí Ọlọ́run yàn ti ń ṣàkóso lọ́run. Jòhánù kìlọ̀ pé àwọn “ẹlẹ́tàn” máa pọ̀ gan-an, wọ́n á sì máa ṣi àwọn tí kò gba Jèhófà àti Jésù gbọ́ lọ́nà. (2 Jòh. 7-11) Jòhánù sọ pé: “Ta ni òpùrọ́ tí kì í bá ṣe ẹni tó sọ pé Jésù kọ́ ni Kristi?” (1 Jòh. 2:22) Ohun kan ṣoṣo tí ò ní jẹ́ kí wọ́n tàn wá jẹ ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Ó dìgbà tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ ká tó mọ Jèhófà àti Jésù. (Jòh. 17:3) Ohun tó sì máa jẹ́ kó dá wa lójú pé òtítọ́ la gbà gbọ́ nìyẹn. w20.07 21 ¶4-5

Tuesday, April 5

Ẹ pinnu pé ẹ ò ní fi ohun ìkọ̀sẹ̀ . . . síwájú arákùnrin yín.​—Róòmù 14:13.

Ohun kan tá a lè ṣe tá ò fi ní jẹ́ “ohun ìkọ̀sẹ̀” fáwọn tá a jọ ń sáré ìje ìyè yìí ni pé ká ṣe tán láti gba èrò wọn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀ dípò tá a fi máa rin kinkin mọ́ èrò tiwa. (Róòmù 14:19-21; 1 Kọ́r. 8:9, 13) Kókó yìí ló mú ká yàtọ̀ sí àwọn sárésáré inú ayé tí olúkúlùkù wọn ń wá bí òun á ṣe gbégbá orókè. Tara wọn nìkan ni wọ́n máa ń rò. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń ti àwọn míì kó lè jẹ́ pé àwọn ló máa wà níwájú. Àmọ́ àwa Kristẹni kì í bára wa díje. (Gál. 5:26; 6:4) Ohun tó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ ká lè jọ sá eré náà dópin ká sì jọ rí èrè ìyè náà gbà. Ìdí nìyẹn tá a fi ń sa gbogbo ipá wa ká lè fi ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò pé ká máa “wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe [tiwa] nìkan.” (Fílí. 2:4) Nínú eré ìje ìyè tá à ń sá yìí, Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa san èrè ńlá fún wa tá a bá sáré náà dópin. Ó ṣèlérí pé òun á fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun yálà ní ọ̀run tàbí nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. w20.04 28 ¶10; 29 ¶12

Wednesday, April 6

Àwọn yìí ni àwọn tó wá látinú ìpọ́njú ńlá náà.​—Ìfi. 7:14.

Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa fẹsẹ̀ rìn wọnú ayé tuntun. Àwọn tó la ìpọ́njú ńlá náà já máa tún rí ìṣẹ́gun míì lórí ikú, ìyẹn nígbà tí Jèhófà bá jí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó ti kú dìde. Ẹ wo bí inú gbogbo wa ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n bá jíǹde! (Ìṣe 24:15) Àwọn tó bá sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀ máa ṣẹ́gun ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù, wọ́n á sì wà láàyè títí láé. Ó yẹ kí inú gbogbo àwa Kristẹni tá a wà láàyè báyìí máa dùn torí ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ nípa àjíǹde tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé ká ṣe ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé ká jẹ́ kí ọwọ́ wa dí “nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58) Tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ yìí, tá a sì jẹ́ adúróṣinṣin, a máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. Ohun tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú yìí á kọjá àfẹnusọ, á sì jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé làálàá wa kò já sí asán nínú Olúwa. w20.12 13 ¶16-17

Thursday, April 7

Àwọn ọmọ ogun wọn kóra jọ láti bá ẹni tó jókòó sórí ẹṣin àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jagun.​—Ìfi. 19:19.

Ó jọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà ni Ìsíkíẹ́lì 38:10-23; Dáníẹ́lì 2:43-45; 11:44–12:1 àti Ìfihàn 16:13-16, 21 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan tá a máa jíròrò tẹ̀ lé e yìí ló ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀. Lásìkò díẹ̀ lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” máa kóra jọ, wọ́n á sì fìmọ̀ ṣọ̀kan láti ṣe ohun kan. (Ìfi. 16:13, 14) Ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ni Bíbélì pè ní “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.” (Ìsík. 38:2) Wọ́n máa fi gbogbo agbára wọn gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run láti pa wá rẹ́ ráúráú. Nígbà tí Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lásìkò yẹn, ó sọ pé àwọn òkúta yìnyín ńlá máa já bọ́ lu àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kí òkúta yìnyín ìṣàpẹẹrẹ yìí dúró fún àwọn gbankọgbì ọ̀rọ̀ ìdájọ́ táwa èèyàn Jèhófà máa kéde. Ìkéde yìí lè múnú bí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù, kíyẹn sì mú kó gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run pẹ̀lú èrò àtipa wá run pátápátá.​—Ìfi. 16:21. w20.05 15 ¶13-14

Friday, April 8

Tí ẹ̀yin bá mọ bí ẹ ṣe ń fún àwọn ọmọ yín ní ẹ̀bùn tó dáa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín, mélòómélòó wá ni Baba yín tó wà ní ọ̀run, ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!​—Lúùkù 11:13.

Ó yẹ ká mọyì ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́. A lè túbọ̀ fi hàn pé a mọyì ẹ̀mí mímọ́ tá a bá ń ronú nípa àwọn nǹkan ribiribi tó ń gbé ṣe lákòókò wa yìí. Kí Jésù tó pa dà sọ́run, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Ẹ̀mí mímọ́ ti mú kí àwọn mílíọ̀nù mẹ́jọ ààbọ̀ èèyàn máa jọ́sìn Jèhófà níbi gbogbo láyé. A tún ń gbádùn Párádísè tẹ̀mí torí ẹ̀mí mímọ́ mú ká ní àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Àwọn ànímọ́ yìí ló para pọ̀ di “èso ti ẹ̀mí.” (Gál. 5:22, 23) Ẹ ò rí i pé ẹ̀bùn tó ṣeyebíye ni ẹ̀mí mímọ́! w20.05 28 ¶10; 29 ¶13

Saturday, April 9

Bí ikú ṣe wá nípasẹ̀ ẹnì kan, àjíǹde òkú náà wá nípasẹ̀ ẹnì kan.​—1 Kọ́r. 15:21.

Àwọn ìdí kan wà tó jẹ́ ká gbà pé a máa dá àwọn èèyàn wa mọ̀ nígbà tí wọ́n bá jíǹde. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wo àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa àwọn tó jíǹde, ó jọ pé ṣe ni Jèhófà máa fún àwọn tó máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú ní ara tuntun tó jọ èyí tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀, wọ́n á máa sọ̀rọ̀, wọ́n á sì máa ronú bí wọ́n ṣe ń ṣe kí wọ́n tó kú. Ẹ rántí pé Jésù fi ikú wé oorun, ó sì fi àjíǹde wé ìgbà téèyàn jí lójú oorun. (Mát. 9:18, 24; Jòh. 11:11-13) Táwọn èèyàn bá jí lójú oorun, ojú wọn, ohùn wọn àti èrò wọn kì í yàtọ̀ sí bó ṣe rí kí wọ́n tó sùn, kódà wọ́n máa ń rántí ohun tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó lọ sùn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Lásárù. Odindi ọjọ́ mẹ́rin ni Lásárù fi wà nínú ibojì, ara ẹ̀ sì ti ń jẹrà. Síbẹ̀, nígbà tí Jésù jí i dìde, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn arábìnrin rẹ̀ dá a mọ̀, òun náà sì rántí wọn.​—Jòh. 11:38-44; 12:1, 2. w20.08 14 ¶3; 16 ¶8

Sunday, April 10

Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa tó jókòó sórí ìtẹ́ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.​—Ìfi. 7:10.

Láwọn ọ̀nà kan, àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn jọra. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ọ̀kan ju èkejì lọ, àwọn méjèèjì ló ṣeyebíye lójú rẹ̀. Ó ṣe tán, ohun kan náà ló ná Jèhófà láti ra àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn pa dà, ìyẹn ẹ̀mí Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn méjèèjì ni pé àwọn kan ń lọ sọ́run, àwọn kan sì máa wà lórí ilẹ̀ ayé. Èyí ó wù kó jẹ́, àwọn méjèèjì gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti Kristi. (Sm. 31:23) Ká má sì gbàgbé pé Jèhófà lè fún èyíkéyìí nínú àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́ láti gbé nǹkan ribiribi ṣe, yálà a jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí àgùntàn mìíràn. Ìrètí àgbàyanu ni Jèhófà fún gbogbo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀. (Jer. 29:11) Nígbà Ìrántí Ikú Kristi, gbogbo wa máa yin Jèhófà àti Kristi fún ohun tí wọ́n ṣe ká lè gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun. Kò sí àní-àní pé Ìrántí Ikú Kristi ni ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù fáwa Kristẹni tòótọ́. w21.01 18 ¶16; 19 ¶19

Monday, April 11

Ẹ máa ṣe èyí.​—1 Kọ́r. 11:25.

Ó ṣe kedere pé àwọn tó máa gbé láyé ló pọ̀ jù lára àwọn tó máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Kí wá nìdí tí wọ́n fi ń wá? Ṣe lọ̀rọ̀ náà dà bí àwọn tó lọ síbi ìgbéyàwó ọ̀rẹ́ wọn. Wọ́n fẹ́ kí tọkọtaya náà mọ̀ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn sì máa dúró tì wọ́n. Lọ́nà kan náà, àwọn àgùntàn mìíràn máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Kristi àtàwọn ẹni àmì òróró, àwọn sì ń tì wọ́n lẹ́yìn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àgùntàn mìíràn tún ń fi hàn pé àwọn mọrírì ẹbọ ìràpadà Kristi torí wọ́n mọ̀ pé ìyẹn ló máa jẹ́ káwọn lè wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ìdí pàtàkì míì táwọn àgùntàn mìíràn fi ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi ni pé wọ́n ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù. Nígbà tí Jésù dá Ìrántí Ikú rẹ̀ sílẹ̀, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (1 Kọ́r. 11:23-26) Torí náà, àwọn àgùntàn mìíràn á ṣì máa wá síbi Ìrántí Ikú Kristi títí dìgbà tí èyí tó kẹ́yìn lára àwọn ẹni àmì òróró bá lọ sọ́run. w21.01 17-18 ¶13-14

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 9) Jòhánù 12:12-19; Máàkù 11:1-11

Tuesday, April 12

Bí a ṣe fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ wa nìyí, Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sí ayé, ká lè ní ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.​—1 Jòh. 4:9.

Ohun tẹ́nì kan bá ṣe ló máa fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́. (Fi wé Jémíìsì 2:17, 26.) Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. (1 Jòh. 4:19) Báwo la ṣe mọ̀? Àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì ló jẹ́ ká mọ̀. (Sm. 25:10; Róòmù 8:38, 39) Àmọ́ o, kì í ṣe àwọn ohun tó sọ nìkan ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan tó ń ṣe fún wa ló jẹ́ ká gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́. Jèhófà gbà kí Ọmọ ẹ̀ jìyà, kó sì kú nítorí wa. (Jòh. 3:16) Torí náà, ṣé ó tún yẹ ká máa ṣiyèméjì pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa? A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù tá a bá ń ṣègbọràn sí wọn. (Jòh. 14:15; 1 Jòh. 5:3) Jésù sì dìídì pàṣẹ pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní kejì. (Jòh. 13:34, 35) Kò yẹ kó jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wa nìkan làá fi máa sọ fáwọn ará wa pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, ó tún gbọ́dọ̀ hàn nínú ohun tá à ń ṣe.​—1 Jòh. 3:18. w21.01 9 ¶6; 10 ¶8

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 10) Jòhánù 12:20-50

Wednesday, April 13

Mo pè yín ní ọ̀rẹ́.​—Jòh. 15:15.

Àwọn ẹni àmì òróró máa wà pẹ̀lú Jésù títí láé torí pé wọ́n á jọ ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n á wà pẹ̀lú Jésù, wọ́n á rí i lójúkojú, wọ́n á jọ máa sọ̀rọ̀, wọ́n á sì jọ máa ṣe nǹkan pọ̀. (Jòh. 14:2, 3) Bákan náà, Jésù máa fìfẹ́ hàn sáwọn tó máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, á sì máa bójú tó wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ní rí Jésù lójúkojú, àjọṣe tó wà láàárín wọn á túbọ̀ máa lágbára bí wọ́n ṣe ń gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun tí Jèhófà àti Jésù mú kó ṣeé ṣe fún wọn. (Àìsá. 9:6, 7) Tá a bá gbà láti di ọ̀rẹ́ Jésù, ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí. Bí àpẹẹrẹ, à ń jàǹfààní nísinsìnyí bó ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa tó sì ń tì wá lẹ́yìn. Yàtọ̀ síyẹn, a tún láǹfààní láti wà láàyè títí láé lọ́jọ́ iwájú. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù máa jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ ẹni tó ga jù lọ láyé àti lọ́run, ìyẹn Jèhófà Baba Jésù. Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ la ní bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù! w20.04 25 ¶15-16

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 11) Lúùkù 21:1-36

Thursday, April 14

A ó sọ gbogbo èèyàn di ààyè nínú Kristi.​—1 Kọ́r. 15:22.

Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní Kọ́ríńtì tí wọ́n máa jíǹde sí ọ̀run ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí. A sọ àwọn Kristẹni yẹn ‘di mímọ́ nínú Kristi Jésù, a sì pè wọ́n láti jẹ́ ẹni mímọ́.’ Ó tún mẹ́nu kan “àwọn tó ti sun oorun ikú nínú Kristi.” (1 Kọ́r. 1:2; 15:18; 2 Kọ́r. 5:17) Nínú lẹ́tà míì tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ, ó sọ pé àwọn tó “wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú [Jésù] lọ́nà tó gbà kú” máa “wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ lọ́nà tó gbà jíǹde.” (Róòmù 6:3-5) Ọlọ́run jí Jésù dìde ní ẹ̀dá ẹ̀mí, ó sì lọ sọ́run. Ohun kan náà ni Ọlọ́run máa ṣe fún gbogbo àwọn tó wà “nínú Kristi,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Pọ́ọ̀lù sọ pé a ti gbé Kristi dìde, òun sì ni “àkọ́so nínú àwọn tó ti sùn nínú ikú.” (1 Kọ́r. 15:20) Jésù lẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run jí dìde ní ẹ̀dá ẹ̀mí tó sì fún ní ìyè àìnípẹ̀kun. w20.12 5-6 ¶15-16

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 12) Mátíù 26:1-5, 14-16; Lúùkù 22:1-6

ỌJỌ́ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
Lẹ́yìn Tí Oòrùn Bá Wọ̀
Friday, April 15

A . . . máa wà pẹ̀lú Olúwa nígbà gbogbo.​—1 Tẹs. 4:17.

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí àwọn ẹni àmì òróró tó wà láyé báyìí bá kú ni wọ́n máa jíǹde lọ sọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fìdí èyí múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tó sọ ní 1 Kọ́ríńtì 15:51, 52. Àwọn arákùnrin Kristi yìí máa láyọ̀ gan-an lẹ́yìn tí wọ́n bá jíǹde. Bíbélì sọ iṣẹ́ tí àwọn tó máa yí pa dà “ní ìpajúpẹ́” máa ṣe ní ọ̀run. Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹni tó bá ṣẹ́gun, tó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ mi títí dé òpin ni màá fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn, kó lè fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ bí ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, bí mo ṣe gbà á lọ́wọ́ Baba mi gẹ́lẹ́.”​—Ìfi. 2:26, 27. w20.12 12 ¶14-15

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 13) Mátíù 26:17-19; Máàkù 14:12-16; Lúùkù 22:7-13 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 14) Jòhánù 13:1-5; 14:1-3

Saturday, April 16

A ti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú.​—1 Kọ́r. 15:20.

Bí Pọ́ọ̀lù ṣe pe Jésù ní “àkọ́so” fi hàn pé Ọlọ́run máa jí àwọn míì náà dìde sí ọ̀run, ìyẹn àwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì tí wọ́n wà “nínú Kristi.” (1 Kọ́r. 15:18) Tó bá yá, Ọlọ́run máa jí àwọn náà dìde ní ẹ̀dá ẹ̀mí lọ sí ọ̀run bíi ti Jésù. Ọlọ́run ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í jí àwọn tó wà “nínú Kristi” sí ọ̀run nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ará Kọ́ríńtì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé ọjọ́ iwájú nìyẹn máa ṣẹlẹ̀, ó ní: “Kálukú wà ní àyè rẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹ́yìn náà àwọn tó jẹ́ ti Kristi nígbà tó bá wà níhìn-ín.” (1 Kọ́r. 15:23; 1 Tẹs. 4:15, 16) Ìgbà wíwà níhìn-ín Kristi la wà báyìí. Torí náà, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ti kú máa ní láti dúró dìgbà wíwà níhìn-ín rẹ̀ kí wọ́n tó lè gba èrè wọn ti ọ̀run kí wọ́n sì “wà níṣọ̀kan pẹ̀lú [Jésù] lọ́nà tó gbà jíǹde.”​—Róòmù 6:5. w20.12 5 ¶12; 6 ¶16-17

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 14) Jòhánù 19:1-42

Sunday, April 17

A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́; a gbé e dìde ní àìdíbàjẹ́.​—1 Kọ́r. 15:42.

Àwọn tí Ọlọ́run máa jí dìde sí ọ̀run pẹ̀lú “ara tẹ̀mí” ni Pọ́ọ̀lù ń sọ. (1 Kọ́r. 15:43, 44) Nígbà tí Jésù wà láyé, irú ara tá a ní yìí lòun náà ní. Àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run jí i dìde, ó “di ẹ̀mí tó ń fúnni ní ìyè” ó sì pa dà sí ọ̀run. Bíi ti Jésù, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró náà máa di ẹ̀dá ẹ̀mí lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá jí wọn dìde. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí a ṣe gbé àwòrán ẹni tí a fi erùpẹ̀ dá wọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni a máa gbé àwòrán ẹni ti ọ̀run wọ̀.” (1 Kọ́r. 15:45-49) Ẹ fi sọ́kàn pé nígbà tí Jèhófà jí Jésù dìde, ara ti ẹ̀mí ló fún un. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún Ìjọba Ọlọ́run” ní ọ̀run. (1 Kọ́r. 15:50) Èyí fi hàn pé nígbà tí Jèhófà bá jí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn ẹni àmì òróró yòókù dìde, wọn ò ní gbé ara tó ń díbàjẹ́ yìí àti ẹ̀jẹ̀ lọ sí ọ̀run. w20.12 10-11 ¶10-12

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 15) Mátíù 27:62-66 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 16) Jòhánù 20:1

Monday, April 18

Ikú, ìṣẹ́gun rẹ dà? Ikú, oró rẹ dà?​—1 Kọ́r. 15:55.

Ọlọ́run mí sí mélòó kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní láti sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde ti ọ̀run. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “A ti wá di ọmọ Ọlọ́run, àmọ́ a ò tíì fi ohun tí a máa jẹ́ hàn kedere. A mọ̀ pé nígbà tí a bá fi í hàn kedere a máa dà bíi rẹ̀.” (1 Jòh. 3:2) Torí náà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ò mọ báwọn ṣe máa rí gan-an nígbà tí Ọlọ́run bá jí wọn dìde sí ọ̀run pẹ̀lú ara ti ẹ̀mí. Àmọ́, wọ́n máa rí Jèhófà nígbà tí wọ́n bá gba èrè wọn ní ọ̀run, Bíbélì sì ṣe àwọn àlàyé kan nípa ẹ̀. Àwọn ẹni àmì òróró máa wà pẹ̀lú Kristi nígbà tó bá “sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo àṣẹ àti agbára di asán,” títí kan “ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Jésù àtàwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ á fi ara wọn àti ohun gbogbo sábẹ́ Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:24-28) Ó dájú pé àsìkò yẹn máa lárinrin gan-an! w20.12 8 ¶2

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi:(Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 16) Jòhánù 20:2-18

Tuesday, April 19

Mo ní ìrètí . . . pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.​—Ìṣe 24:15.

Ọlọ́run máa jí àwọn Kristẹni tí ò nírètí àtilọ sí ọ̀run náà dìde. Bíbélì sọ pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì tó nírètí láti gbé lọ́run máa ní “àjíǹde àkọ́kọ́ kúrò nínú ikú.” (Fílí. 3:11) Èyí fi hàn pé àjíǹde míì máa wà lẹ́yìn ìyẹn. Ohun tí Jóòbù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ pé Ọlọ́run máa rántí òun lọ́jọ́ iwájú. (Jóòbù 14:15) “Àwọn tó jẹ́ ti Kristi nígbà tó bá wà níhìn-ín” máa wà pẹ̀lú Jésù lọ́run nígbà tó bá sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo àṣẹ àti agbára di asán. Kódà, “ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn” máa di asán. Ó dájú pé àwọn tó jíǹde sí ọ̀run máa bọ́ lọ́wọ́ ikú tá a jogún. (1 Kọ́r. 15:23-26) Àwọn tó nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé lè máa retí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú ohun tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Ó dájú pé kò sí aláìṣòdodo kankan tó máa lọ sọ́run. Torí náà, àjíǹde orí ilẹ̀ ayé ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí. w20.12 6-7 ¶18-19

Wednesday, April 20

[Kristi] nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.​—Gál. 2:20.

A lè máa ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe mọ̀ pé Jèhófà lè dárí jì mí?’ Ti pé o béèrè ìbéèrè yẹn fi hàn pé Jèhófà lè dárí jì ẹ́. Lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Ilé Ìṣọ́ kan sọ pé: “A lè máa ṣàṣìṣe kan náà lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè jẹ́ ìwà kan tó ti mọ́ wa lára ká tó rí òtítọ́, tá a sì gbà pé a ti borí ẹ̀. . . . Má ṣe ronú pé Jèhófà ò lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ náà jì ẹ́ láé àti láéláé. Fi sọ́kàn pé bí Sátánì ṣe fẹ́ kó o máa ronú nìyẹn. Ti pé ọ̀rọ̀ náà ń bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́, tó sì ń mú kó o máa bínú sí ara ẹ fi hàn pé o kì í ṣe èèyàn burúkú àti pé Jèhófà máa dárí jì ẹ́. Máa tọ Jèhófà lọ nígbà gbogbo, má jẹ́ kó sú ẹ. Yíjú sí i tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, kó o sì bẹ̀ ẹ́ taratara pé kó dárí jì ẹ́, kó wẹ̀ ẹ́ mọ́, kó sì ràn ẹ́ lọ́wọ́.” Kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, ó ti hu àwọn ìwà burúkú sẹ́yìn. Pọ́ọ̀lù rántí àwọn nǹkan tó ṣe. (1 Tím. 1:12-15) Àmọ́, ó gbà pé torí òun ni Kristi ṣe kú. Torí náà, Pọ́ọ̀lù ò dá ara ẹ̀ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà látìgbà yẹn lọ. w20.11 27 ¶14; 29 ¶17

Thursday, April 21

Tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì máa fún un, torí ó lawọ́ sí gbogbo èèyàn, kì í sì í pẹ̀gàn tó bá ń fúnni.​—Jém. 1:5.

Onírúurú nǹkan ni Sátánì lè fi dẹ wá wò. Kí ló yẹ ká ṣe? Ó lè máa ṣe wá bíi pé kò burú jù. Bí àpẹẹrẹ, a lè ronú pé: ‘Ó ṣe tán, kì í ṣe ohun tí wọ́n lè tìtorí ẹ̀ yọ mí lẹ́gbẹ́, torí náà kò burú jù.’ Èrò òdì gbáà nìyẹn. Torí náà, ó máa dáa ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé kì í ṣe pé Sátánì ń wá bó ṣe máa pín ọkàn mi níyà? Tí n bá ṣe ohun tí ọkàn mi ń fà sí yìí, ṣé mi ò ní kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà? Ṣérú ìwà bẹ́ẹ̀ máa mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ni àbí á mú kí n jìnnà sí i?’ Ó yẹ kó o ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìbéèrè yìí. Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n tí wàá fi lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí láìtan ara ẹ jẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní kó sínú ìdẹwò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwọ náà á lè ṣe bíi ti Jésù tó sọ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!” (Mát. 4:10) Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé a ò ní jàǹfààní kankan tá a bá jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà. w20.06 12-13 ¶16-17

Friday, April 22

Mo sọ fún gbogbo ẹni tó wà láàárín yín níbẹ̀ pé kó má ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, àmọ́ kó máa ronú lọ́nà tó fi hàn pé ó láròjinlẹ̀.​—Róòmù 12:3.

Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tá a ní ń mú ká ṣègbọràn sí Jèhófà torí a mọ̀ pé àwọn ìlànà rẹ̀ ló dáa jù fún wa. (Éfé. 4:22-24) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yìí kan náà ló ń jẹ́ ká fi ìfẹ́ Jèhófà ṣáájú tiwa ká sì gbà pé àwọn míì sàn jù wá lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, a ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn ará wa. (Fílí. 2:3) Àmọ́ o, tá ò bá ṣọ́ra àwọn èèyàn ayé lè mú ká di agbéraga àti ẹni tí kò mọ̀ ju tara ẹ̀ lọ. Ó jọ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní torí nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó sọ pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tó wà láàárín yín níbẹ̀ pé kó má ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, àmọ́ kó máa ronú lọ́nà tó fi hàn pé ó láròjinlẹ̀.” Pọ́ọ̀lù sọ pé kò yẹ ká ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ, àmọ́ kì í ṣe pé ká wá ro ara wa pin bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Torí náà, tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, àá wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì a ò sì ní ro ara wa ju bó ti yẹ lọ. w20.07 2 ¶1-2

Saturday, April 23

Kò sí ìyọlẹ́nu ní ilẹ̀ náà, wọn kò sì bá a jagun.​—2 Kíró. 14:6.

Nígbà tó yá, àlàáfíà tó wà nígbà ìṣàkóso Ásà dópin. Ìdí ni pé àwọn ọmọ ogun alágbára tó tó mílíọ̀nù kan ṣígun wá láti ilẹ̀ Etiópíà. Ó sì dá Síírà ọ̀gágun wọn lójú pé òun máa fi Júdà ṣèfà jẹ. Àmọ́ Jèhófà ni Ásà gbẹ́kẹ̀ lé, kì í ṣe àwọn ọmọ ogun tó ní. Ásà bẹ Jèhófà pé: “Ràn wá lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé, a wá ní orúkọ rẹ láti dojú kọ ọ̀pọ̀ èèyàn yìí.” (2 Kíró. 14:11) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Etiópíà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì àwọn ọmọ ogun Júdà, Ásà gbà pé Jèhófà lágbára láti ran àwọn lọ́wọ́, ó sì máa gba àwọn èèyàn Rẹ̀ là. Jèhófà kò sì já a kulẹ̀ torí pé Jèhófà àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ fọ́ àwọn èèyàn náà sí wẹ́wẹ́. (2 Kíró. 14:8-13) Lóòótọ́ a ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, àmọ́ ó dá wa lójú pé àsìkò àlàáfíà táwa èèyàn Jèhófà ní báyìí máa tó dópin. Kódà Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ‘gbogbo orílẹ̀-èdè máa kórìíra’ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun.​—Mát. 24:9. w20.09 17-18 ¶14-16

Sunday, April 24

Mò ń láyọ̀ . . . nínú ìwọ̀sí.​—2 Kọ́r. 12:10.

Kò sí ẹni tó fẹ́ kí wọ́n fi ìwọ̀sí lọ òun tàbí kí wọ́n kan òun lábùkù. Àmọ́, tó bá jẹ́ gbogbo ìgbà là ń ronú nípa àbùkù táwọn alátakò fi ń kàn wá, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì. (Òwe 24:10) Torí náà, ojú wo ló yẹ ká fi wò ó? Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó yẹ ká máa “láyọ̀ . . . nínú ìwọ̀sí.” Kí nìdí? Torí pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá, àwọn èèyàn máa tàbùkù sí wa, wọ́n á fi ìwọ̀sí lọ̀ wá, kódà wọ́n á ṣe inúnibíni sí wa. Ìyẹn sì wà lára ohun tó ń fi hàn pé lóòótọ́ la jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi. (1 Pét. 4:14) Ó ṣe tán, Jésù ti sọ pé wọ́n máa ṣe inúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn òun. (Jòh. 15:18-20) Tẹ́ ò bá sì gbàgbé, ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ojú àbùkù làwọn Gíríìkì fi máa ń wo àwọn Kristẹni. Kódà, ojú táwọn Júù fi wo Pétérù àti Jòhánù náà ni wọ́n fi wo gbogbo àwọn Kristẹni yòókù, wọ́n gbà pé “wọn ò kàwé àti pé wọ́n jẹ́ gbáàtúù.” (Ìṣe 4:13) Àwọn èèyàn gbà pé àwọn Kristẹni ò lágbára torí pé wọn kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, wọn kì í sì í dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ológun kankan, torí náà wọn ò lẹ́nu láwùjọ. Ṣé ọ̀rọ̀ àbùkù táwọn alátakò ń sọ sáwọn Kristẹni yẹn mú kí wọ́n dá iṣẹ́ ìwàásù dúró? Rárá. w20.07 14-15 ¶3-4

Monday, April 25

Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa, torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá, gbogbo ẹni tó bá sì nífẹ̀ẹ́ la ti bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì mọ Ọlọ́run.​—1 Jòh. 4:7.

Ọ̀rọ̀ àwọn ará ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní jẹ àpọ́sítélì Jòhánù lógún gan-an, ó sì fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára. Àwọn lẹ́tà mẹ́ta tó kọ sí wọn jẹ́ ká rí bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó. Inú wa dùn gan-an pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń fìfẹ́ hàn bíi ti Jòhánù ni Jèhófà yàn láti bá Kristi jọba lọ́run! (1 Jòh. 2:27) Ẹ jẹ́ ká fi àwọn ìmọ̀ràn tí Jòhánù fún wa sọ́kàn. Pinnu pé wàá máa rìn nínú òtítọ́, wàá sì máa ṣègbọràn sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ. Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì nígbàgbọ́ nínú ohun tó ò ń kọ́. Ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jésù. Sá fún ọgbọ́n orí èèyàn àti ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà. Má ṣe ohun táá jẹ́ kó o máa díbọ́n bíi pé ò ń sin Jèhófà nígbà tó jẹ́ pé ò ń dẹ́ṣẹ̀. Jẹ́ kí àwọn ìlànà Jèhófà máa darí ẹ lójoojúmọ́. Máa dárí ji àwọn ará, kó o sì máa ran àwọn tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́ kí wọ́n lè dúró nínú òtítọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀ láìka ìṣòro tàbí inúnibíni tó o lè kojú sí, ìwọ àtàwọn ará yòókù á máa bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́. w20.07 24-25 ¶15-17

Tuesday, April 26

Ọlọ́run ti to ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan bí ó ṣe fẹ́ sínú ara.​—1 Kọ́r. 12:18.

Jèhófà fún gbogbo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láǹfààní láti wà nínú ìjọ rẹ̀. Òótọ́ ni pé ojúṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ní nínú ìjọ, àmọ́ gbogbo wa pátá la wúlò. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé kò sẹ́nì kankan nínú àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tó yẹ kó wo ẹlòmíì nínú ìjọ sùn-ùn, kó wá sọ pé: “Mi ò nílò rẹ.” (1 Kọ́r. 12:21) Tí àlàáfíà bá máa wà nínú ìjọ, ó ṣe pàtàkì pé ká mọyì ara wa ká sì wà níṣọ̀kan. (Éfé. 4:16) Tá a bá ń ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan, ìfẹ́ á wà láàárín wa, kò sì ní sẹ́ni tó máa ronú pé òun ò wúlò nínú ìjọ. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ló yan gbogbo àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ. Síbẹ̀ ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ní, ohun tí wọ́n sì lágbára láti ṣe ò dọ́gba. (1 Kọ́r. 12:17) Bí àpẹẹrẹ, kò pẹ́ táwọn kan di alàgbà, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ nírìírí. Àwọn míì lára wọn ti dàgbà, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ lókun. Síbẹ̀, kò yẹ kí alàgbà kankan wo alàgbà míì sùn-ùn, kó wá sọ pé “Mi ò nílò rẹ.” Dípò bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kí gbogbo alàgbà fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Róòmù 12:10 sílò. w20.08 26 ¶1-2; 27 ¶4

Wednesday, April 27

Ìrísí ayé yìí ń yí pa dà.​—1 Kọ́r. 7:31.

Jèhófà ń lo apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀ láti máa darí wa lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Tí ètò Ọlọ́run bá sọ òye tuntun tá a ní nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì kan, a máa ń tẹ́wọ́ gbà á. Tí wọ́n bá sì tọ́ wa sọ́nà nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà, a máa ń fi ìtọ́ni náà sílò. Àmọ́, báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tí ètò Ọlọ́run bá ṣàtúnṣe bí kí wọ́n ta Gbọ̀ngàn Ìjọba tá à ń lò? Àá máa láyọ̀ tá a bá ń rántí pé Jèhófà là ń ṣiṣẹ́ fún àti pé òun ló ń darí ètò yìí. (Kól. 3:23, 24) Àpẹẹrẹ àtàtà ni Dáfídì fi lélẹ̀ fún wa nígbà tó kówó sílẹ̀ pé kí wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì. Ó sọ pé: “Ta ni mí, ta sì ni àwọn èèyàn mi, tí a fi máa láǹfààní láti ṣe ọrẹ àtinúwá bí irú èyí? Nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, ohun tó ti ọwọ́ rẹ wá ni a sì fi fún ọ.” (1 Kíró. 29:14) Tá a bá ń fi owó ṣètìlẹ́yìn, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé àtinú ohun tí Jèhófà fún wa la ti ń ṣe ọrẹ náà. Síbẹ̀, Jèhófà mọyì gbogbo àkókò, okun àti ohunkóhun tá a bá yọ̀ǹda láti fi ti iṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn.​—2 Kọ́r. 9:7. w20.11 22-23 ¶14-16

Thursday, April 28

Ẹni tó bá . . . ń wo ṣíṣú òjò kò ní kórè.​—Oníw. 11:4.

Kì í ṣe iye àwọn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ràn lọ́wọ́ láti wá sínú ètò Jèhófà la fi ń díwọ̀n pé a ṣàṣeyọrí. (Lúùkù 8:11-15) Tá a bá ń wàásù, tá a sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láìjẹ́ kó sú wa, Jèhófà máa gbà pé a ṣàṣeyọrí. Kí nìdí? Ìdí ni pé à ń ṣègbọràn sí òun àti Jésù ọmọ rẹ̀. (Máàkù 13:10; Ìṣe 5:28, 29) Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa torí pé òpin ti sún mọ́lé ju ti ìgbàkígbà rí lọ! Àkókò tá a ní láti wàásù ká sì gba àwọn èèyàn là ti dín kù gan-an. Torí náà, má fi iṣẹ́ ìwàásù falẹ̀ rárá, má sì ronú pé ó dìgbà tí nǹkan bá rọrùn fún ẹ kó o tó lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà. Ní báyìí, ṣe ohun táá jẹ́ kó túbọ̀ máa wù ẹ́ láti wàásù, túbọ̀ máa fi kún ìmọ̀ tó o ní, ṣe ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ nígboyà, kó o sì máa kó ara ẹ níjàánu. Dara pọ̀ mọ́ àwọn apẹja èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ tí wọ́n ń wàásù kárí ayé. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí ìdùnnú Jèhófà. (Neh. 8:10; Lúùkù 5:10) Paríparí ẹ̀, pinnu pé wàá máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù títí dìgbà tí Jèhófà bá sọ pé ó tó. w20.09 7 ¶18-20

Friday, April 29

Máa ṣọ́ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ.​—1 Tím. 6:20.

A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn nǹkan tara gbà wá lọ́kàn débi tá ò fi ní gbájú mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa mọ́. Tá ò bá ṣọ́ra, “agbára ìtannijẹ ọrọ̀” lè paná ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà, a lè má mọyì òtítọ́ inú Bíbélì mọ́, ó sì lè má yá wa lára láti sọ ọ́ fáwọn èèyàn mọ́. (Mát. 13:22) Tá a bá fẹ́ dáàbò bo ohun tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wa, ó yẹ ká mọ ohun tá a máa ṣe tá a bá kíyè sóhun tó lè ṣèpalára fún wa. Tá a bá ń wo fíìmù tàbí tá à ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó yẹ ká ti ronú ohun tá a máa ṣe tí àwòrán ìṣekúṣe tàbí eré oníwà ipá tàbí èrò àwọn apẹ̀yìndà bá ṣàdédé yọjú. Tá a bá ti múra sílẹ̀, àá tètè gbé ìgbésẹ̀ káwọn nǹkan yẹn má bàa ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́, ká sì jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà. (Sm. 101:3; 1 Tím. 4:12) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ àwọn ohun iyebíye tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wa, ìyẹn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì àti àǹfààní tá a ní láti fi kọ́ àwọn míì. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ìgbésí ayé wa máa nítumọ̀, àá sì láyọ̀ bá a ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà. w20.09 30 ¶16-19

Saturday, April 30

O sì máa fi ojú ara rẹ rí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá.​—Àìsá. 30:20.

Ṣé o ti ṣèrìbọmi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o ti sọ lójú gbogbo èèyàn pé o nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, o sì ti ṣe tán láti máa jọ́sìn pẹ̀lú ètò tó ń darí. Lónìí, Jèhófà ń darí ètò rẹ̀ lọ́nà tó jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́, àwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe àtàwọn ìlànà rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo mẹ́ta lára ohun tó jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àti bó ṣe hàn nínú ètò rẹ̀. Àkọ́kọ́, “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” (Ìṣe 10:34) Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó fún wa ní Ọmọ rẹ̀ láti ṣe ‘ìràpadà fún gbogbo èèyàn.’ (1 Tím. 2:6; Jòh. 3:16) Jèhófà ń mú káwọn èèyàn rẹ̀ wàásù fún gbogbo ẹni tó ṣe tán láti gbọ́, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní nínú ìràpadà náà. Ìkejì, Ọlọ́run ètò àti àlàáfíà ni Jèhófà. (1 Kọ́r. 14:33, 40) Torí náà, ó yẹ káwa tá à ń jọ́sìn ẹ̀ wà létòlétò, kí àlàáfíà sì wà láàárín wa. Ìkẹta, Jèhófà ni “Olùkọ́ [wa] Atóbilọ́lá.” (Àìsá. 30:21) Ìdí nìyẹn tí ètò rẹ̀ fi ń sapá gan-an láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn nínú ìjọ àti lóde ẹ̀rí. w20.10 20 ¶1-3

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́