ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es22 ojú ìwé 47-57
  • May

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • May
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Sunday, May 1
  • Monday, May 2
  • Tuesday, May 3
  • Wednesday, May 4
  • Thursday, May 5
  • Friday, May 6
  • Saturday, May 7
  • Sunday, May 8
  • Monday, May 9
  • Tuesday, May 10
  • Wednesday, May 11
  • Thursday, May 12
  • Friday, May 13
  • Saturday, May 14
  • Sunday, May 15
  • Monday, May 16
  • Tuesday, May 17
  • Wednesday, May 18
  • Thursday, May 19
  • Friday, May 20
  • Saturday, May 21
  • Sunday, May 22
  • Monday, May 23
  • Tuesday, May 24
  • Wednesday, May 25
  • Thursday, May 26
  • Friday, May 27
  • Saturday, May 28
  • Sunday, May 29
  • Monday, May 30
  • Tuesday, May 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
es22 ojú ìwé 47-57

May

Sunday, May 1

Ó . . . ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.​—Lúùkù 2:51.

Àtìgbà tí Jésù ti wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti pinnu pé òun á máa ṣègbọràn sáwọn òbí òun. Kò kọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu rí, kó wá máa ronú pé òun gbọ́n jù wọ́n lọ. Torí pé Jésù ni àkọ́bí, kò sí àní-àní pé ó fi ọwọ́ gidi mú ojúṣe tó ní. Ó dájú pé ó fojú sí iṣẹ́ tí Jósẹ́fù bàbá rẹ̀ kọ́ ọ kó lè ti ìdílé wọn lẹ́yìn. Ó ṣeé ṣe káwọn òbí Jésù sọ àwọn nǹkan ìyanu tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bí Jésù fún un àtohun táwọn áńgẹ́lì sọ nípa ẹ̀. (Lúùkù 2:8-19, 25-38) Yàtọ̀ sóhun tí àwọn òbí rẹ̀ sọ fún un, Jésù fúnra ẹ̀ fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé? Ohun tó wáyé láàárín òun àtàwọn olùkọ́ tó wà ní Jerúsálẹ́mù ló jẹ́ ká mọ̀. Bíbélì ròyìn pé “ẹnu ń ya gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí òye tó ní àti bó ṣe ń dáhùn.” (Lúùkù 2:46, 47) Kódà, ọmọ ọdún méjìlá (12) péré ni nígbà tó ti dá a lójú pé Jèhófà ni Bàbá òun.​—Lúùkù 2:42, 43, 49. w20.10 29-30 ¶13-14

Monday, May 2

A ti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú.​—1 Kọ́r. 15:12.

Àjíǹde Jésù ló mú ká gbà pé àwọn míì náà máa jíǹde. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde, ó mẹ́nu ba kókó pàtàkì mẹ́ta: (1) “Kristi kú nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (2) Wọ́n “sin ín.” (3) Ọlọ́run “jí i dìde ní ọjọ́ kẹta bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ.” (1 Kọ́r. 15:3, 4) Kí ni ikú Jésù, bí wọ́n ṣe sin ín àti àjíǹde rẹ̀ máa ṣe fún wa? Wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa mú Mèsáyà “kúrò lórí ilẹ̀ alààyè” àti pé wọ́n máa “sin ín pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú.” Kò tán síbẹ̀ o. Àìsáyà tún fi kún un pé Mèsáyà máa ru “ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn.” Jésù mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ nígbà tó fi ẹ̀mí ẹ̀ rà wá pa dà. (Àìsá. 53:8, 9, 12; Mát. 20:28; Róòmù 5:8) Torí náà, ikú Jésù, bí wọ́n ṣe sin ín àti àjíǹde rẹ̀ ló mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé a máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú àti pé a máa pa dà rí àwọn èèyàn wa tó ti kú. w20.12 2-3 ¶4-6; 5 ¶11

Tuesday, May 3

Tí a bá rí ẹnikẹ́ni tó ní ìdí láti gbẹ́kẹ̀ lé ẹran ara, èmi gan-an ní. Tí ẹlòmíì bá sì rò pé òun ní ìdí láti gbẹ́kẹ̀ lé ẹran ara, tèmi jù bẹ́ẹ̀.​—Fílí. 3:4.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wàásù nínú sínágọ́gù àwọn Júù. Bí àpẹẹrẹ, ó wàásù nínú sínágọ́gù tó wà ní Tẹsalóníkà, ó “bá [àwọn Júù] fèròwérò látinú Ìwé Mímọ́ fún sábáàtì mẹ́ta.” (Ìṣe 17:1, 2) Ó ṣeé ṣe kí ọkàn Pọ́ọ̀lù balẹ̀ nínú sínágọ́gù náà torí pé Júù lòun náà. (Ìṣe 26:4, 5) Ẹ̀rù ò ba Pọ́ọ̀lù láti wàásù fáwọn Júù torí ó mọ̀ wọ́n dáadáa. (Fílí. 3:5) Lẹ́yìn táwọn alátakò lé Pọ́ọ̀lù kúrò ní Tẹsalóníkà àti Bèróà, ó lọ sí Áténì. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe ẹ̀, “ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn Júù àti àwọn míì tó ń jọ́sìn Ọlọ́run fèròwérò nínú sínágọ́gù.” (Ìṣe 17:17) Àmọ́ nígbà tó ń wàásù fáwọn èèyàn níbi ọjà, ó pàdé àwọn èèyàn míì tó yàtọ̀. Lára wọn ni àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí àtàwọn Kèfèrí míì tó gbà pé “ẹ̀kọ́ tuntun” ni Pọ́ọ̀lù fi ń kọ́ àwọn. Wọ́n wá sọ fún un pé: “Àwọn ohun tó ṣàjèjì sí etí wa lò ń sọ.”​—Ìṣe 17:18-20. w20.04 9 ¶5-6

Wednesday, May 4

Nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tó burú ló máa ń wà lọ́kàn mi.​—Róòmù 7:21.

Má ṣe ro ara ẹ pin tó o bá láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan tó ò ń bá yí. Ká máa rántí pé, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run nípasẹ̀ ìràpadà ni Jèhófà ń wò mọ́ wa lára tó fi kà wá sí olódodo, kì í ṣe nípa iṣẹ́ rere èyíkéyìí tá a ṣe. (Éfé. 1:7; 1 Jòh. 4:10) A tún lè jẹ́ káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n máa tẹ́tí sí wa nígbà tá a bá ń tú ọkàn wa jáde, wọ́n sì máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ táá gbé wa ró. (Òwe 12:25; 1 Tẹs. 5:14) Arábìnrin Joy lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tóun náà máa ń rẹ̀wẹ̀sì sọ pé: “Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ará, ìrẹ̀wẹ̀sì ì bá ti bò mí mọ́lẹ̀. Báwọn ará ṣe ràn mí lọ́wọ́ mú kó dá mi lójú pé Jèhófà gbọ́ àdúrà mi. Kódà, wọ́n ti jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè fún àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì níṣìírí.” Àmọ́ o, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn ará wa lè má mọ̀gbà tá a nílò ìṣírí. Torí náà, ó lè gba pé ká sún mọ́ àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tá à ń bá yí. w20.12 23-24 ¶7-8

Thursday, May 5

Mo pè yín ní ọ̀rẹ́.​—Jòh. 15:15.

Kó o tó lè di ọ̀rẹ́ ẹnì kan, ó ṣe pàtàkì kó o lo àkókò pẹ̀lú onítọ̀hún, kẹ́ ẹ sì jọ máa sọ̀rọ̀. Bẹ́ ẹ ṣe jọ ń sọ̀rọ̀, tẹ́ ẹ sì ń sọ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí yín, bẹ́ẹ̀ lẹ ṣe máa túbọ̀ mọwọ́ ara yín. Àmọ́ tó bá di pé ká di ọ̀rẹ́ Jésù kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Ọ̀kan lára ohun tó lè mú kó ṣòro láti dọ̀rẹ́ Jésù ni pé a ò rí Jésù sójú. Bó ṣe rí fún ọ̀pọ̀ Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà nìyẹn. Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i báyìí, síbẹ̀ ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.” (1 Pét. 1:8) Torí náà, ó ṣeé ṣe ká di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jésù bá ò tiẹ̀ rí i rí. Ohun míì ni pé a ò lè bá Jésù sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Tá a bá ń gbàdúrà, Jèhófà là ń bá sọ̀rọ̀. Lóòótọ́ a máa ń gbàdúrà lórúkọ Jésù, àmọ́ kì í ṣe òun là ń bá sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Kódà, Jésù gan-an ò fẹ́ ká gbàdúrà sí òun. Kí nìdí? Ìdí ni pé àdúrà wà lára ìjọsìn wa, Jèhófà nìkan ló sì yẹ ká jọ́sìn. (Mát. 4:10) Síbẹ̀, a ṣì lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jésù. w20.04 20 ¶1-3

Friday, May 6

[Ọlọ́run] máa fún yín lókun, ó máa sọ yín di alágbára.​—1 Pét. 5:10.

Onírúurú ìṣòro làwọn sárésáré ilẹ̀ Gíríìsì àtijọ́ máa ń ní. Bí àpẹẹrẹ, ó lè rẹ̀ wọ́n, ara sì lè máa ro wọ́n. Àmọ́ gbogbo ohun tí wọ́n gbára lé kò ju ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà àti okun tí wọ́n ní. Bíi tiwọn, àwa náà gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe máa sá eré ìje ìyè náà. Àmọ́ a ní àǹfààní kan táwọn sárésáré yẹn ò ní. A lè gbára lé Jèhófà tó jẹ́ orísun agbára tí kò láfiwé. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé Jèhófà máa dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nìkan, á tún mú ká túbọ̀ lágbára! Ọ̀pọ̀ ìṣòro ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kojú. Yàtọ̀ sí pé àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ burúkú sí i tí wọ́n sì ṣenúnibíni sí i, àwọn ìgbà kan wà tó rẹ̀ ẹ́ tó sì tún fara da ‘ẹ̀gún kan tó wà nínú ara rẹ̀.’ (2 Kọ́r. 12:7) Àmọ́ dípò tó fi máa jẹ́ káwọn ìṣòro yẹn mú kóun juwọ́ sílẹ̀, ṣe ló kà á sí àǹfààní láti túbọ̀ gbára lé Jèhófà. (2 Kọ́r. 12:9, 10) Torí pé Pọ́ọ̀lù gbára lé Jèhófà tí kò sì juwọ́ sílẹ̀, Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti fara da gbogbo ìṣòro tó ní. w20.04 29 ¶13-14

Saturday, May 7

Kò sí èèyàn tó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba . . . fà á.​—Jòh. 6:44.

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń bá Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ṣiṣẹ́. (2 Kọ́r. 6:1) Gbogbo ìgbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù là ń bá wọn ṣiṣẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ nípa ara rẹ̀ àtàwọn míì tó ń wàásù pé: “Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá.” (1 Kọ́r. 3:9) A tún ń bá Jésù ṣiṣẹ́ nígbàkigbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ẹ rántí ohun tí Jésù sọ lẹ́yìn tó pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” ó ní: “Mo wà pẹ̀lú yín.” (Mát. 28:19, 20) Àwọn áńgẹ́lì náà ńkọ́? Bíbélì fi hàn pé wọ́n ń darí wa bá a ṣe ń kéde “ìhìn rere àìnípẹ̀kun . . . fún àwọn tó ń gbé ayé.” A mà dúpẹ́ o! (Ìfi. 14:6) Àwọn nǹkan wo la ti gbé ṣe torí pé Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́? Bá a ṣe ń fúnrúgbìn ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àwọn kan ń bọ́ sí ọkàn rere, wọ́n sì ń hù. (Mát. 13:18, 23) Ta ló ń mú kí irúgbìn òtítọ́ náà hù kó sì so èso? Jésù ṣàlàyé ẹ̀ nínú ẹsẹ̀ ojúmọ́ wa tòní. w20.05 30 ¶14-15

Sunday, May 8

Ẹ má sì jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí máa darí yín.​—Róòmù 12:2.

Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló ń kọ ara wọn sílẹ̀ lónìí. Kóńkó jabele kálukú ló ń ṣe tiẹ̀ lọ̀rọ̀ àwọn ìdílé míì bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jọ ń gbé lábẹ́ òrùlé kan náà. Ọkùnrin kan tó máa ń gba àwọn ìdílé nímọ̀ràn sọ pé: “Àwọn òbí kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè bá ara wọn àtàwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀. Bí wọn ò sí nídìí tẹlifíṣọ̀n, wọ́n á máa tẹ fóònù tàbí kọ̀ǹpútà, bẹ́ẹ̀ sì làwọn ọmọ á máa gbá géèmù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìdílé yìí ń gbé pa pọ̀, wọn ò mọra wọn rárá.” Nínú ayé, àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Torí náà, ó yẹ ká sapá kí wọ́n má bàa kó èèràn ràn wá. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa ká lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn tá a jọ wà nínú ìdílé, ká sì jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará wa túbọ̀ jinlẹ̀. (Róòmù 12:10) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé kí àwa àti àwọn míì ní àjọṣe tímọ́tímọ́, irú èyí tó máa ń wà láàárín àwọn ọmọ ìyá. Irú ìfẹ́ yìí ló yẹ ká ní fún àwọn ará wa, ó ṣe tán, ọmọ ìyá la jẹ́ nípa tẹ̀mí. Tá a bá ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara wa lẹ́nì kìíní kejì, ìyẹn á jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ.​—Míkà 2:12. w21.01 20 ¶1-2

Monday, May 9

Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀ kí n lè máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.​—Sm. 86:11.

Tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan bá fìmọ̀ ṣọ̀kan, wọ́n máa ṣàṣeyọrí, àmọ́ kò dájú pé àwọn tí kò fìmọ̀ ṣọ̀kan máa ṣàṣeyọrí. Tó bá jẹ́ pé bó o ṣe máa sin Jèhófà tó o sì máa múnú ẹ̀ dùn ló gbà ẹ́ lọ́kàn, tí èrò yìí sì ń darí gbogbo ohun tó ò ń ṣe, ọkàn ẹ ò ní pínyà, wàá sì ṣàṣeyọrí bíi ti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù yẹn. Máa rántí pé Sátánì ń wá bó ṣe máa pín ọkàn rẹ níyà. Ó ń wá bó ṣe lè máa darí èrò rẹ, ohun tọ́kàn rẹ ń fà sí àti bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ kó o lè rú òfin Jèhófà. Ìwọ alára sì mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí ọkàn rẹ ṣọ̀kan kó o tó lè sin Jèhófà. (Mát. 22:36-38) Torí náà, má ṣe jẹ́ kí Sátánì pín ọkàn rẹ níyà! Gbàdúrà sí Jèhófà bíi ti Dáfídì tó sọ pé: “Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀ kí n lè máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.” Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa fọ̀rọ̀ inú àdúrà yẹn sílò lójoojúmọ́. Jẹ́ kó máa hàn nínú gbogbo ìpinnu rẹ pé ò ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ Jèhófà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá fi hàn pé ẹlẹ́rìí lo jẹ́ fún Jèhófà lóòótọ́. (Òwe 27:11) Bákan náà, gbogbo wa á lè sọ bíi ti wòlíì Míkà pé: “Àwa yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa títí láé àti láéláé.”​—Míkà 4:5. w20.06 13 ¶17-18

Tuesday, May 10

Ó máa fi ìbínú tó le gan-an jáde lọ láti pani rẹ́ ráúráú, kó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ run.​—Dán. 11:44.

Nígbà tí ọba àríwá àtàwọn ìjọba ayé yòókù bá gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run, inú máa bí Ọlọ́run Olódùmarè, ìyẹn ló sì máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 16:14, 16) Lásìkò yẹn, Jèhófà máa pa ọba àríwá run, kò sì “sẹ́ni tó máa ràn án lọ́wọ́.” Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ìjọba tó para pọ̀ jẹ́ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù. (Dán. 11:45) Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ọba àríwá àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ ṣe máa pa run àti bí Jèhófà ṣe máa dá àwa èèyàn rẹ̀ nídè. (Dán. 12:1) Kí ni ẹsẹ yìí túmọ̀ sí? Máíkẹ́lì ni orúkọ míì tí Jésù Kristi Ọba wa ń jẹ́. Àtọdún 1914 tí Ọlọ́run ti fìdí Ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lọ́run ni Máíkẹ́lì ti ń “dúró nítorí” àwa èèyàn Jèhófà. Láìpẹ́, ó “máa dìde” tàbí lédè míì á gbèjà àwa èèyàn Jèhófà, á sì pa àwọn ọ̀tá run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Ogun yẹn ló máa kẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Dáníẹ́lì sọ pé ó máa wáyé ní “àkókò wàhálà” tó burú jù nínú ìtàn ẹ̀dá.​—Ìfi. 6:2; 7:14. w20.05 15-16 ¶15-17

Wednesday, May 11

Wọ́n . . . mú Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì.​—Jẹ́n. 39:1.

Ìwọ̀nba lohun tí Jósẹ́fù lè ṣe nígbà tó jẹ́ ẹrú àti nígbà tó wà lẹ́wọ̀n. Àmọ́ kí ló ṣe tí ìrẹ̀wẹ̀sì yẹn ò fi bò ó mọ́lẹ̀? Dípò táá fi máa ronú lórí àwọn nǹkan tí ò lè ṣe mọ́, ṣe ló gbájú mọ́ iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un. Bí Jósẹ́fù ṣe máa mú inú Jèhófà dùn ló gbà á lọ́kàn. Jèhófà náà sì bù kún gbogbo ohun tí Jósẹ́fù dáwọ́ lé. (Jẹ́n. 39:21-23) Ìtàn Jósẹ́fù kọ́ wa pé ìwà ìkà ló kúnnú ayé yìí. Torí náà, àwọn èèyàn lè hùwà àìdáa sí wa, kódà ẹnì kan tá a jọ ń sin Jèhófà lè ṣe ohun tó dùn wá. Àmọ́ tá a bá fi Jèhófà ṣe Àpáta tàbí Ibi Ààbò wa, a ò ní rẹ̀wẹ̀sì tàbí ká fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀. (Sm. 62:6, 7; 1 Pét. 5:10) Ẹ má sì gbàgbé pé nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ni Jósẹ́fù nígbà tí Jèhófà jẹ́ kó lá àwọn àlá méjì tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà fọkàn tán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lónìí ló dà bíi Jósẹ́fù torí pé àwọn náà nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Kódà, wọ́n ti ju àwọn kan lára wọn sẹ́wọ̀n láìṣẹ̀ láìrò torí wọ́n pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà làwọn máa ṣe.​—Sm. 110:3. w20.12 16 ¶3; 17 ¶5, 7

Thursday, May 12

Wọ́n pe àwọn àpọ́sítélì, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù mọ́.​—Ìṣe 5:40.

Wọ́n fìyà jẹ àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù torí pé wọ́n ń tẹ̀ lé Jésù wọ́n sì ń wàásù ọ̀rọ̀ rẹ̀, síbẹ̀ ṣe ni inú àwọn àpọ́sítélì yẹn ń dùn. (Ìṣe 4:18-21; 5:27-29, 41, 42) Ojú ò ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ò kà wọ́n sí, iṣẹ́ ìwàásù wọn ṣàǹfààní fáwọn èèyàn ju ohun táwọn alátakò ṣe fáwọn èèyàn lọ. Bí àpẹẹrẹ, ìwé táwọn kan lára àwọn Kristẹni yẹn kọ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó sì fún wọn nírètí. Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n wàásù ti ń ṣàkóso báyìí, ó sì máa ṣàkóso gbogbo ayé láìpẹ́. (Mát. 24:14) Àmọ́ àwọn alákòóso tó ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni nígbà yẹn ti roko ìgbàgbé, wọ́n ti dìtàn. Bákan náà, àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn ìgbà yẹn wà lọ́run báyìí, tí wọ́n ń ṣàkóso. Àmọ́, àwọn alátakò yẹn ti kú fin-ín fin-ín, tí wọ́n bá sì jíǹde rárá lọ́jọ́ iwájú, abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run táwọn Kristẹni yẹn wàásù rẹ̀ ni wọ́n máa wà.​—Ìfi. 5:10. w20.07 15 ¶4

Friday, May 13

[Ábúráhámù] ń retí ìlú tó ní ìpìlẹ̀ tòótọ́, tí Ọlọ́run ṣètò, tó sì kọ́.​—Héb. 11:10.

Ábúráhámù nígbàgbọ́ tó lágbára débi pé ṣe ló dà bíi pé ó ń rí Ẹni Àmì Òróró tàbí Mèsáyà tó máa di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fáwọn Júù ìgbà ayé ẹ̀ pé: “Ábúráhámù bàbá yín yọ̀ gidigidi bó ṣe ń retí láti rí ọjọ́ mi, ó rí i, ó sì yọ̀.” (Jòh. 8:56) Èyí fi hàn pé ó dá Ábúráhámù lójú pé àwọn kan lára àtọmọdọ́mọ òun máa wà nínú Ìjọba tí Jèhófà á fìdí ẹ̀ múlẹ̀, Ábúráhámù sì ṣe tán láti dúró de Ìjọba náà. Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé ìlú tí Ọlọ́run dá sílẹ̀, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run lòun ń dúró dè? Lákọ̀ọ́kọ́, Ábúráhámù ò dara pọ̀ mọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè èyíkéyìí. Kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló ń ṣí kiri dípò kó jókòó sójú kan kó sì máa bá àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú wọn ṣèjọba. Yàtọ̀ síyẹn, Ábúráhámù ò gbé ìjọba tiẹ̀ kalẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ń ṣègbọràn sí Jèhófà, ó sì ń fi sùúrù dúró de àwọn ìlérí rẹ̀. Ohun tí Ábúráhámù ṣe yìí fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. w20.08 3 ¶4-5

Saturday, May 14

Ẹni tó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.​—Róòmù 6:7.

Jèhófà ṣèlérí pé kò sẹ́ni tó ń gbé lábẹ́ àkóso Kristi tó máa sọ pé: “Ara mi ò yá.” (Àìsá. 33:24) Torí náà, ara tó jí pépé ni Jèhófà máa fún àwọn táá jí dìde. Àmọ́ kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n máa dẹni pípé. Torí pé tí wọ́n bá di pípé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn èèyàn wọn lè má dá wọn mọ̀. Ó jọ pé díẹ̀díẹ̀ ni aráyé máa di pípé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Lẹ́yìn tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá parí, Jésù máa dá Ìjọba pa dà fún Baba rẹ̀. Nígbà yẹn, gbogbo ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn ni Ìjọba náà á ti ṣe, títí kan sísọ àwa èèyàn di pípé. (1 Kọ́r. 15:24-28; Ìfi. 20:1-3) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára wa tá a bá ń kí àwọn tó jíǹde káàbọ̀! Ṣé inú ẹ tó dùn máa mú kó o bú sẹ́kún tàbí ṣe ni wàá máa rẹ́rìn-ín? Ṣó máa mú kó o bú sórin ayọ̀ sí Jèhófà? Èyí ó wù ó jẹ́, ó dájú pé inú gbogbo wa máa dùn torí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ fi hàn sí wa bí wọ́n ṣe jí àwọn òkú dìde. w20.08 16-17 ¶9-10

Sunday, May 15

Kálukú ló ní ẹ̀bùn tirẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ọ̀kan lọ́nà yìí, òmíràn lọ́nà yẹn.​—1 Kọ́r. 7:7.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n ronú àtisin Jèhófà láìṣègbéyàwó. (1 Kọ́r. 7:8, 9) Kò sí àní-àní pé Pọ́ọ̀lù kò fojú pa àwọn tí kò ṣègbéyàwó rẹ́. Kódà ojúṣe pàtàkì ló gbé fún Tímótì tó jẹ́ ọ̀dọ́ tí kò sì tíì ṣègbéyàwó. (Fílí. 2:19-22) Torí náà, kò ní bójú mu kó jẹ́ torí pé arákùnrin kan ṣègbéyàwó tàbí kò ṣègbéyàwó la máa fi pinnu bóyá ó kúnjú ìwọ̀n fún iṣẹ́ nínú ìjọ tàbí kò kúnjú ìwọ̀n. (1 Kọ́r. 7:32-35, 38) Kò sígbà kankan tí Jésù tàbí Pọ́ọ̀lù sọ pé dandan ni káwọn Kristẹni ṣègbéyàwó tàbí kí wọ́n má ṣe bẹ́ẹ̀. Kí wá la lè sọ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn ṣègbéyàwó tàbí kó má ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ gbọ́ ohun tí Ilé Ìṣọ́ October 1, 2012 sọ lórí kókó yìí, ó ní: “Ní tòdodo, ipò méjèèjì [ìyẹn kéèyàn ṣègbéyàwó tàbí kó má ṣe bẹ́ẹ̀] la lè sọ pé ó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. . . . Jèhófà kò ka [wíwà láìní ọkọ tàbí aya] sí nǹkan ìtìjú tàbí ìbànújẹ́.” Torí náà, ó yẹ ká mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí kò tíì ṣègbéyàwó, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. w20.08 28 ¶8-9

Monday, May 16

Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n, . . . àfi Baba nìkan.​—Mát. 24:36.

Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ó máa ń yá àwọn èèyàn lára láti gbọ́ ìhìn rere. Kódà, ṣe ló dà bíi pé ohun tí wọ́n nílò gan-an nìyẹn. Láwọn ilẹ̀ míì, àwọn èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. Kí làwọn èèyàn máa ń ṣe lágbègbè yín? Yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé ká máa wàásù nìṣó títí iṣẹ́ náà máa fi parí. Tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù náà máa parí, “òpin yóò [sì] dé.” (Mát. 24:14) Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn nǹkan táá máa ṣẹlẹ̀ táá jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn nǹkan yìí sì lè mú ká má pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìwàásù mọ́. Torí náà, ó kìlọ̀ fún wa pé ká “máa ṣọ́nà.” (Mát. 24:42) Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí jọ àwọn nǹkan tí kò jẹ́ káwọn èèyàn tẹ́tí sí Nóà nígbà tó ń kìlọ̀ fún wọn. (Mát. 24:37-39; 2 Pét. 2:5) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká gbájú mọ́ iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa. w20.09 8 ¶1-2, 4

Tuesday, May 17

Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.​—2 Tím. 3:12.

Sátánì “ń bínú gidigidi,” torí náà ṣe là ń tan ara wa jẹ tá a bá ń ronú pé kò ní fìkanra mọ́ wa. (Ìfi. 12:12) Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, gbogbo wa pátá la máa kojú àdánwò. Bíbélì sọ pé “ìpọ́njú ńlá máa wà nígbà náà, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di báyìí.” (Mát. 24:21) Tó bá dìgbà yẹn, àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè ṣenúnibíni sí wa, ìjọba sì lè fòfin de iṣẹ́ wa. (Mát. 10:35, 36) Bíi ti Ọba Ásà, ṣé a máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ kó sì dáàbò bò wá? (2 Kíró. 14:11) Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń múra wa sílẹ̀ de ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀. Ó ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa fún wa ní “oúnjẹ [tẹ̀mí] ní àkókò tó yẹ” ká lè máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó láìka àdánwò tó lè dé bá wa sí. (Mát. 24:45) Àmọ́ o, ká tó lè nígbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú Jèhófà, a gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa.​—Héb. 10:38, 39. w20.09 18 ¶16-18

Wednesday, May 18

Ọkàn ọba dà bí odò ní ọwọ́ Jèhófà. Ibi tí Ó bá fẹ́ ló ń darí rẹ̀ sí.​—Òwe 21:1.

Jèhófà lè lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú kí àwọn tó wà nípò àṣẹ ṣe ohun tó fẹ́ tó bá bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Àwọn èèyàn lè gbẹ́lẹ̀ láti mú kí odò kan ṣàn gba ibi tí wọ́n bá fẹ́. Lọ́nà kan náà, Jèhófà lè lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti darí ọkàn àwọn alákòóso lọ́nà tó fi jẹ́ pé wọ́n á ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Tí Jèhófà bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn aláṣẹ máa ń ṣe àwọn ìpinnu tó máa ṣe àwọn èèyàn Ọlọ́run láǹfààní. (Fi wé Ẹ́sírà 7:21, 25, 26.) Kí làwa lè ṣe? A lè gbàdúrà fún “àwọn ọba àti gbogbo àwọn tó wà ní ipò àṣẹ” tó bá di pé kí wọ́n ṣe ìpinnu tó máa kan ìgbésí ayé wa àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (1 Tím. 2:1, 2, àlàyé ìsàlẹ̀; Neh. 1:11) Bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwa náà máa ń gbàdúrà kíkankíkan fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wà lẹ́wọ̀n.​—Ìṣe 12:5; Héb. 13:3. w20.11 15 ¶13-14

Thursday, May 19

Ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.​—Mát. 28:19.

Tó bá jẹ́ pé ìwọ lo kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, wàá láyọ̀ lọ́jọ́ tó bá ṣèrìbọmi! (1 Tẹs. 2:19, 20) Ṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ṣèrìbọmi dà bíi “lẹ́tà ìdámọ̀ràn” fún àwọn tó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ àti fún ìjọ lápapọ̀. (2 Kọ́r. 3:1-3) Ó wú wa lórí pé lọ́dún mẹ́rin tẹ̀léra, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì là ń ṣe lóṣooṣù kárí ayé. Láàárín àwọn ọdún yẹn kan náà, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé ọgọ́rin (280,000) ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún tí wọ́n sì ń di ọmọlẹ́yìn Kristi. Kí la lè ṣe láti ran èyí tó pọ̀ jù lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí lọ́wọ́ kí wọn lè ṣèrìbọmi? Torí pé Jèhófà ṣì ń mú sùúrù fún àwọn èèyàn tó sì ń fún wọn láǹfààní láti di ọmọ ẹ̀yìn, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tètè ṣèrìbọmi. Ìdí sì ni pé àkókò tó kù ò tó nǹkan mọ́!​—1 Kọ́r. 7:29a; 1 Pét. 4:7. w20.10 6 ¶1-2

Friday, May 20

Ọlọ́run dojú ìjà kọ àwọn agbéraga, àmọ́ ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.​—Jém. 4:6.

Ọba Sọ́ọ̀lù ò ṣègbọràn sí Jèhófà. Kódà, Sọ́ọ̀lù ò gbà pé òun jẹ̀bi nígbà tí wòlíì Sámúẹ́lì kò ó lójú lórí ọ̀rọ̀ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń wí àwíjàre pé ohun tóun ṣe ò fi bẹ́ẹ̀ burú, ó sì tún di ẹ̀bi ru àwọn míì. (1 Sám. 15:13-24) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, kì í ṣèyẹn nìgbà àkọ́kọ́ tí Sọ́ọ̀lù máa ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Sám. 13:10-14) Ó dunni pé Sọ́ọ̀lù jẹ́ kí ìgbéraga wọ òun lẹ́wù. Torí pé kò tún èrò ẹ̀ ṣe, Jèhófà bá a wí, ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ká má bàa dà bíi Sọ́ọ̀lù, ó yẹ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí: ‘Tí mo bá rí ìmọ̀ràn tó yẹ kí n fi sílò nínú Ìwé Mímọ́, ṣé mo máa ń ṣàwáwí? Ṣé mo máa ń fojú kéré ìwà àìtọ́ tí mo hù? Ṣé mo máa ń di ẹ̀bi ohun tí mo ṣe ru àwọn míì?’ Tí ìdáhùn wa sí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè yẹn bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, a jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ ṣàtúnṣe sí èrò àti ìwà wa. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìgbéraga máa wọ̀ wá lẹ́wù, ìyẹn á sì mú kí Jèhófà kọ̀ wá lọ́rẹ̀ẹ́. w20.11 20 ¶4-5

Saturday, May 21

Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nígbà ọ̀dọ́ rẹ, kí àwọn ọjọ́ wàhálà tó dé, kí àwọn ọdún náà tó dé nígbà tí wàá sọ pé: “Wọn ò mú inú mi dùn.”​—Oníw. 12:1.

Ẹ̀yìn ọ̀dọ́, ẹ pinnu ẹni tẹ́ ẹ máa sìn. Ìwọ fúnra ẹ gbọ́dọ̀ mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́, ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe àtohun tó fẹ́ kó o fayé ẹ ṣe. (Róòmù 12:2) Ìgbà yẹn ni wàá tó lè ṣèpinnu tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé ẹ, ìyẹn sì ni pé kó o sin Jèhófà. (Jóṣ. 24:15) Tó o bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, wàá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìgbàgbọ́ ẹ á sì túbọ̀ lágbára. Pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà ni wàá fi sípò àkọ́kọ́ láyé ẹ. Ohun tí ayé Sátánì ń sọ ni pé tó o bá ń lo ẹ̀bùn tó o ní fún àǹfààní ara ẹ, wàá láyọ̀. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé ṣe làwọn tó ń lé nǹkan ìní tara máa ń “fi ìrora tó pọ̀ gún gbogbo ara wọn.” (1 Tím. 6:9, 10) Lọ́wọ́ kejì, tó o bá gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu, tó o sì pinnu pé ìfẹ́ rẹ̀ ni wàá fi sípò àkọ́kọ́ láyé ẹ, wàá ṣàṣeyọrí, wàá sì “máa hùwà ọgbọ́n.”​—Jóṣ. 1:8. w20.10 30-31 ¶17-18

Sunday, May 22

Mo . . . gbọ́dọ̀ kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run . . . , torí pé nítorí èyí la ṣe rán mi.​—Lúùkù 4:43.

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ìhìn rere tí Jésù wàásù rẹ̀ mú kí gbogbo èèyàn nírètí. Ó pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa bá iṣẹ́ tóun bẹ̀rẹ̀ lọ, kí wọ́n sì wàásù “títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Àmọ́ wọn ò lè dá ṣiṣẹ́ náà. Torí náà, wọ́n nílò ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn “olùrànlọ́wọ́” tí Jésù ṣèlérí pé òun máa fún wọn. (Jòh. 14:26; Sek. 4:6) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí ẹ̀mí mímọ́ gbà ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 S.K. Kété lẹ́yìn tí wọ́n rí ẹ̀mí mímọ́ gbà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, kò sì pẹ́ tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn fi di ọmọlẹ́yìn Jésù. (Ìṣe 2:41; 4:4) Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí wọn, dípò káwọn ọmọ ẹ̀yìn náà bẹ̀rù, ṣe ni wọ́n bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Wọ́n gbàdúrà pé: “Jẹ́ kí àwa ẹrú rẹ máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ nìṣó pẹ̀lú ìgboyà.” Ẹ̀yìn náà ni ẹ̀mí mímọ́ bà lé wọn, wọ́n sì ń “fi ìgboyà sọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”​—Ìṣe 4:18-20, 29, 31. w20.10 21 ¶4-5

Monday, May 23

Kristi kú nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ; àti pé . . . a jí i dìde.​—1 Kọ́r. 15:​3, 4.

Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà jí Jésù dìde? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́rìí sí i pé Jésù jíǹde. (1 Kọ́r. 15:5-7) Ẹni àkọ́kọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ó rí Jésù ni àpọ́sítélì Pétérù (tàbí Kéfà). Àwọn ọmọlẹ́yìn kan jẹ́rìí sí i pé Pétérù rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde. (Lúùkù 24:33, 34) Yàtọ̀ síyẹn “àwọn Méjìlá náà,” ìyẹn àwọn àpọ́sítélì rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde. Lẹ́yìn náà, Kristi “fara han èyí tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe ní Gálílì bó ṣe wà nínú Mátíù 28:16-20. Nígbà tó yá, Jésù “fara han Jémíìsì” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbúrò ẹ̀ tí kò gbà tẹ́lẹ̀ pé Òun ni Mèsáyà. (Jòh. 7:5) Lẹ́yìn tí Jémíìsì rí Jésù, ó gbà pé òun ni Mèsáyà. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí ní nǹkan bí ọdún 55 S.K., ọ̀pọ̀ àwọn tó rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde ló ṣì wà láyé. Torí náà, tí ẹnikẹ́ni bá ń ṣiyèméjì, ó lè kàn sí èyíkéyìí lára wọn. w20.12 3 ¶5, 7-8

Tuesday, May 24

Jèhófà yóò fún un lókun lórí ibùsùn àìsàn rẹ̀.​—Sm. 41:3.

Ìrẹ̀wẹ̀sì lè bá wa tá a bá ń ṣàìsàn, pàápàá tó bá jẹ́ àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́. Torí náà, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè má wò wá sàn lọ́nà ìyanu, ó ń tù wá nínú, ó sì ń fún wa lókun ká lè fara da àìsàn tó ń ṣe wá. (Sm. 94:19) Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú kí àwọn ará ìjọ wa bá wa ṣe iṣẹ́ ilé. Ó lè mú kí wọ́n gbàdúrà pẹ̀lú wa, ó sì lè mú ká rántí àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú ká rántí bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú ayé tuntun níbi tá ò ti ní máa ṣàìsàn, tí kò sì ní sí ìrora èyíkéyìí mọ́. (Róòmù 15:4) Àmọ́, ó lè máa ṣe wá bíi pé ìwọ̀nba la lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù báyìí. Àpẹẹrẹ kan ni ti arábìnrin kan tó ń jẹ́ Laurel lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ní onírúurú ìṣòro. Ó ní àrùn jẹjẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà ló ṣe iṣẹ́ abẹ, kòkòrò sì bo ara ẹ̀. Kódà, ẹ̀rọ ló fi ń mí fún odindi ọdún mẹ́tàdínlógójì (37)! Àmọ́ àwọn ìṣòro yìí ò ní kó má wàásù. Bó ṣe ń wàásù fáwọn nọ́ọ̀sì náà ló ń wàásù fáwọn tó ń tọ́jú rẹ̀ nínú ilé. Ó kéré tán, àwọn mẹ́tàdínlógún (17) ló ràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́! w20.12 24 ¶9; 25 ¶12

Wednesday, May 25

Jèhófà wà lẹ́yìn mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?​—Sm. 118:6.

Ohun kan ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Kristẹni. Àwọn èèyàn gbá a mú, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sẹ́yìn tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè pa á. Lọ́jọ́ kejì tí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù wá síwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn, díẹ̀ ló kù káwọn ọ̀tá yìí fa Pọ́ọ̀lù ya. (Ìṣe 21:30-32; 22:30; 23:6-10) Lásìkò yẹn, ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù máa ronú pé ‘Ṣé ẹ̀mí mi ò ní bọ́ báyìí?’ Báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́? Ní òru ọjọ́ tí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù, Jésù “Olúwa” dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Mọ́kàn le! Nítorí pé bí o ṣe ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa mi ní Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ lo ṣe máa jẹ́rìí ní Róòmù.” (Ìṣe 23:11) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn bọ́ sásìkò gan-an ni! Jésù gbóríyìn fún Pọ́ọ̀lù torí bó ṣe jẹ́rìí nípa òun ní Jerúsálẹ́mù. Ó sì ṣèlérí fún un pé á dé Róòmù, á sì túbọ̀ jẹ́rìí nípa òun níbẹ̀. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí, ó dájú pé ọkàn Pọ́ọ̀lù máa balẹ̀ bí ọmọ jòjòló kan tí bàbá ẹ̀ gbé mọ́ra. w20.11 12 ¶1, 3; 13 ¶4

Thursday, May 26

A ní ìrètí yìí . . . , ó dájú, ó [sì] fìdí múlẹ̀.​—Héb. 6:19.

Ìrètí tá a ní dà “bí ìdákọ̀ró fún ọkàn” wa torí ó máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ tá a bá kojú ìṣòro tàbí tí àníyàn bá gbà wá lọ́kàn. Máa ronú nípa àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọjọ́ iwájú níbi tí ò ti ní sí ohunkóhun táá máa kó wa lọ́kàn sókè mọ́. (Àìsá. 65:17) Yàtọ̀ síyẹn, fojú inú wo ara rẹ nínú ayé tuntun níbi tí ò ti ní sí ìṣòro èyíkéyìí tàbí ìdààmú mọ́. (Míkà 4:4) Bákan náà, ìrètí tó o ní á túbọ̀ dá ẹ lójú tó o bá ń sọ nípa ẹ̀ fáwọn míì. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ‘ìrètí náà á dá ẹ lójú ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ títí dé òpin.’ (Héb. 6:11) Bí òpin ayé burúkú yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, ó ṣeé ṣe ká túbọ̀ kojú àwọn ìṣòro táá kó wa lọ́kàn sókè. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà dípò òye tiwa, àá lè kojú àwọn ìṣòro yìí, ọkàn wa á sì balẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe pé: “Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.”​—Àìsá. 30:15. w21.01 7 ¶17-18

Friday, May 27

Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.​—Jém. 5:11.

Ẹ kíyè sí i pé lẹ́yìn tí Jémíìsì 5:11 sọ pé Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó tún sọ ohun míì tó jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ìyẹn ni pé ó jẹ́ aláàánú. (Ẹ́kís. 34:6) Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fàánú hàn sí wa ni pé ó máa ń dárí jì wá tá a bá ṣàṣìṣe. (Sm. 51:1) Nínú Bíbélì, ká fàánú hàn kọjá pé ká dárí ji ẹnì kan. Ó tún gba pé ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn míì máa jẹ wá lọ́kàn, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Nígbà tí Jèhófà ń sọ bó ṣe máa ń wù ú láti ràn wá lọ́wọ́, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ tóun ní sí wa kọjá èyí tí abiyamọ máa ń ní sí ọmọ ẹ̀ lọ. (Àìsá. 49:15) Tá a bá wà nínú ìṣòro, Jèhófà máa ń ṣàánú wa, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 37:39; 1 Kọ́r. 10:13) Àwa náà lè ṣàánú àwọn ará wa tá a bá ń dárí jì wọ́n, tá ò sì dì wọ́n sínú tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá. (Éfé. 4:32) Àmọ́, ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà fàánú hàn sáwọn ará wa ni pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́, ká sì dúró tì wọ́n nígbà ìṣòro. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fara wé Jèhófà tí ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ ò láfiwé.​—Éfé. 5:1. w21.01 21 ¶5

Saturday, May 28

Kristi . . . fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín kí ẹ lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.​—1 Pét. 2:21.

Olórí ìdílé kan kò gbọ́dọ̀ ṣe àṣejù. Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ gba àkókò òun débi pé kò ní ráyè bójú tó ìdílé rẹ̀ nípa tẹ̀mí àti láwọn ọ̀nà míì, ó sì máa ń tọ́ wọn sọ́nà. Jèhófà máa ń tọ́ wa sọ́nà, ó sì máa ń bá wa wí ká lè sunwọ̀n sí i. (Héb. 12:7-9) Bíi ti Jèhófà, Jésù náà máa ń fìfẹ́ tọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ́nà. (Jòh. 15:14, 15) Kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, síbẹ̀ kì í le koko mọ́ wọn. (Mát. 20:24-28) Ó mọ̀ pé aláìpé ni wá àti pé a lè ṣàṣìṣe. (Mát. 26:41) Bíi ti Jèhófà àti Jésù, ó yẹ kí olórí ìdílé kan máa rántí pé aláìpé làwọn tó wà nínú ìdílé òun, wọ́n sì lè ṣàṣìṣe. Torí náà, kò ní máa bínú lódìlódì sí ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀. (Kól. 3:19) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa rántí pé aláìpé ni òun náà, ìyẹn á sì mú kó “fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́” tọ́ wọn sọ́nà bí Gálátíà 6:1 ṣe sọ. Bíi ti Jésù, ó mọ̀ pé ìwà tóun bá hù làwọn yòókù máa tẹ̀ lé. w21.02 6-7 ¶16-18

Sunday, May 29

Kí gbogbo ohun tó ń mí yin Jáà.​—Sm. 150:6.

Ìràpadà tí Jèhófà ṣètò ló fi ra ẹ̀mí gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ àtàwọn míì tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù. (Máàkù 10:45; Ìṣe 20:28; 1 Kọ́r. 15:21, 22) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé Jésù tó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ ni Jèhófà yàn ṣe orí ìjọ. Torí pé Jésù ni orí ìjọ, ó láṣẹ láti ṣòfin kó sì rí i dájú pé gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ń tẹ̀ lé òfin náà, yálà nínú ìdílé tàbí nínú ìjọ. (Gál. 6:2) Àmọ́ kì í ṣe òfin nìkan ni Jésù ń ṣe, ó tún ń bọ́ wa, ó sì ń ṣìkẹ́ wa. (Éfé. 5:29) Àwọn arábìnrin lè fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún Kristi tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí àwọn ọkùnrin tó ń múpò iwájú bá fún wọn. Àwọn arákùnrin lè fi hàn pé àwọn mọyì ètò ipò orí tí Jèhófà ṣe tí wọ́n bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn arábìnrin tí wọ́n sì ń pọ́n wọn lé. Tí gbogbo wa bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò ipò orí tí Jèhófà ṣe, àlàáfíà máa wà nínú ìjọ. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a máa mú ìyìn àti ògo wá fún Jèhófà Baba wa ọ̀run. w21.02 18-19 ¶14-17

Monday, May 30

Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.​—1 Sám. 30:8.

Lásìkò tí Dáfídì àtàwọn ọkùnrin rẹ̀ ń sá fún Sọ́ọ̀lù, wọ́n fi ìdílé wọn sílé láti lọ jagun. Àmọ́ kí wọ́n tó dé, àwọn ọ̀tá ti kó wọn lẹ́rù, wọ́n sì ti kó àwọn ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn lọ. Dáfídì lè ronú pé ṣè bí jagunjagun lòun, kó sì lọ bá àwọn èèyàn náà jà, kó lè gba gbogbo ohun tí wọ́n kó lọ pa dà, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà. Dáfídì bi Jèhófà pé: “Ṣé kí n lépa àwọn jàǹdùkú yìí?” Jèhófà sọ fún Dáfídì pé kó ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì fi dá a lójú pé á ṣẹ́gun. (1 Sám. 30:7-10) Kí lo rí kọ́ nínú ohun tí Dáfídì ṣe yìí? Máa gbàmọ̀ràn kó o tó ṣèpinnu. Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ fọ̀rọ̀ lọ àwọn òbí yín, ẹ sì lè gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn alàgbà tó ní ìrírí. Jèhófà fọkàn tán àwọn alàgbà yìí, ó sì yẹ kíwọ náà ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣe ni Jèhófà fi wọ́n jíǹkí wa nínú ìjọ. Abájọ tí Bíbélì fi pè wọ́n ní “ẹ̀bùn.” (Éfé. 4:8) Tó o bá fara wé ìgbàgbọ́ wọn, tó o sì fi ìmọ̀ràn tí wọ́n fún ẹ sílò, wàá ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu. w21.03 4-5 ¶10-11

Tuesday, May 31

[Kò sí ohunkóhun tó] máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.​—Róòmù 8:​38, 39.

Jésù sọ pé tá ò bá fi ohun tá à ń kọ́ sílò, ṣe la dà bí ọkùnrin kan tó kọ́ ilé ẹ̀ sórí iyẹ̀pẹ̀. Ó ṣiṣẹ́ kára lóòótọ́, àmọ́ àṣedànù ló ṣe. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ilé náà máa wó tí ìjì bá jà, tí àgbàrá omi sì rọ́ lù ú. (Mát. 7:24-27) Lọ́nà kan náà, tá ò bá fi ẹ̀kọ́ tá a kọ́ sílò, ṣe la kàn fi àkókò wa ṣòfò. Tá a bá wá kojú àdánwò tàbí inúnibíni, a ò ní lè dúró. Lọ́wọ́ kejì, tá a bá kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì fohun tá a kọ́ sílò, àá ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ọkàn wa máa balẹ̀, ìgbàgbọ́ wa á sì lágbára. (Àìsá. 48:17, 18) Ká lè jẹ́ olóòótọ́ lójú àdánwò, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ déédéé. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jù tá a lè ṣe ni pé ká máa fògo fún Jèhófà. Torí náà, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé, kò sì sóhun tí ẹnikẹ́ni lè ṣe táá mú kó pa wá tì.​—Héb. 13:5, 6. w21.03 15 ¶6; 18 ¶20

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́