June
Wednesday, June 1
A ti pinnu pé kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan la máa fún yín, a tún máa fún yín ní ara wa.—1 Tẹs. 2:8.
Àwa tá à ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa dénú, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ wá lógún. Gbà pé wọ́n ṣì máa di arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ. Kò rọrùn fún wọn láti pa àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ tì, kí wọ́n sì ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kí wọ́n lè sin Jèhófà. Àwọn tó nírìírí máa ń fojú akẹ́kọ̀ọ́ wọn mọ àwọn tó lè mú kó tẹ̀ síwájú nínú ìjọ. Ìyẹn á mú kó ní àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa láàárín àwa èèyàn Jèhófà, wọ́n á lè fún un níṣìírí, wọ́n á sì lè ràn án lọ́wọ́ tó bá níṣòro. A fẹ́ kí ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ wa balẹ̀ nínú ìjọ kó sì mọ̀ pé apá kan ìjọ lòun náà. A fẹ́ kó mọ̀ pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nífẹ̀ẹ́ òun, kí òun náà sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Ìgbà yẹn ló máa rọrùn fún un láti pa àwọn ọ̀rẹ́ ayé tó ní tẹ́lẹ̀ tì. (Òwe 13:20) Táwọn yẹn bá sì ń fojú burúkú wò ó, ọkàn ẹ̀ á balẹ̀ pé òun láwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ.—Máàkù 10:29, 30; 1 Pét. 4:4. w20.10 17 ¶10-11
Thursday, June 2
Gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé la ti fún mi.—Mát. 28:18.
A gbọ́dọ̀ di ọ̀rẹ́ Jésù ká tó lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ìdí méjì. Àkọ́kọ́, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún yín, torí pé ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi.” (Jòh. 16:27) Ó tún sọ pé: “Kò sí ẹni tó ń wá sọ́dọ̀ Baba àfi nípasẹ̀ mi.” (Jòh. 14:6) Téèyàn bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Jèhófà láìkọ́kọ́ di ọ̀rẹ́ Jésù dà bí ìgbà téèyàn fẹ́ wọnú ilé kan láìgba ẹnu ọ̀nà wọlé. Jésù lo àkàwé yìí nígbà tó sọ pé òun ni “ẹnu ọ̀nà fún àwọn àgùntàn.” (Jòh. 10:7) Ìdí kejì ni pé Jésù gbé àwọn ànímọ́ Baba rẹ̀ yọ lọ́nà tó pé pérépéré. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.” (Jòh. 14:9) Torí náà, ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà mọ Jèhófà ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù. Bá a ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún un á túbọ̀ lágbára. Bá a ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jésù, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún Baba rẹ̀ á túbọ̀ jinlẹ̀. w20.04 21-22 ¶5-6
Friday, June 3
Mò ń láyọ̀ nínú àìlera, . . . torí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, ìgbà náà ni mo di alágbára.—2 Kọ́r. 12:10.
Ṣé ìdùbúlẹ̀ àìsàn lo wà tàbí kẹ̀kẹ́ arọ ni wọ́n fi ń tì ẹ́ kiri? Ṣé orúnkún rẹ ni kì í jẹ́ kó o rìn bó o ṣe fẹ́ àbí o kì í ríran dáadáa? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ wàá lè bá àwọn ọ̀dọ́ tí ara wọn ń ta kébékébé sáré? Ó dájú pé o lè ṣe bẹ́ẹ̀! Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa tó ti dàgbà tára wọn ò sì le ló ń sáré lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Agbára wọn nìkan kò tó láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Wọ́n ń rí okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà bí wọ́n ṣe ń gbádùn àwọn ìpàdé ìjọ látorí fóònù tàbí fídíò. Wọ́n ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn bí wọ́n ṣe ń wàásù fáwọn ìbátan wọn, àwọn dókítà àtàwọn nọ́ọ̀sì. Má ṣe jẹ́ kí àìlera rẹ mú kó o rẹ̀wẹ̀sì débi tí wàá fi ronú pé bóyá ni wàá lè fara da eré ìje náà dópin. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an torí pé o nígbàgbọ́ nínu rẹ̀, ó sì mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe látọdún yìí wá. Àsìkò yìí gan-an lo nílò ìrànwọ́ rẹ̀, kò sì ní pa ọ́ tì láé. (Sm. 9:10) Kódà, ṣe lá túbọ̀ sún mọ́ ẹ. w20.04 29 ¶16-17
Saturday, June 4
Mò ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíì.—1 Kọ́r. 9:23.
Kí lohun tó o lè bá ẹni tó sọ pé òun ní ẹ̀sìn tòun sọ? Ronú ibi tí ọ̀rọ̀ yín ti jọra. Ẹni náà lè gbà pé Ọlọ́run kan ló wà, ó lè gbà pé Jésù ni Olùgbàlà aráyé, ó sì lè gbà pé ọjọ́ ìkẹyìn tá à ń gbé yìí máa tó wá sópin. Tó o bá ti mọ ibi tọ́rọ̀ yín ti jọra, wàá lè wàásù fún un lọ́nà tí ìhìn rere náà á fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Fi sọ́kàn pé àwọn èèyàn lè má gba gbogbo ohun tí ẹ̀sìn wọn fi ń kọ́ wọn gbọ́. Lẹ́yìn tó o bá ti mọ ẹ̀sìn tẹ́nì kan ń ṣe, gbìyànjú láti mọ ohun tí òun fúnra rẹ̀ gbà gbọ́. Arákùnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà kíyè sí i pé àwọn kan máa ń sọ pé àwọn gba Mẹ́talọ́kan gbọ́, àmọ́ wọ́n lè má gbà pé Baba, Ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo. Ó wá fi kún un pé, “ìyẹn máa ń jẹ́ kó rọrùn láti ríbi tí ọ̀rọ̀ wa ti jọra.” Torí náà, gbìyànjú láti mọ ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́ gan-an. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá dà bíi àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó “di ohun gbogbo nítorí gbogbo èèyàn.”—1 Kọ́r. 9:19-22. w20.04 10 ¶9-10
Sunday, June 5
Ní àkókò yẹn, àwọn èèyàn rẹ máa yè bọ́, gbogbo àwọn tí orúkọ wọn wà nínú ìwé.—Dán. 12:1.
Ọkàn wa balẹ̀, a ò sì bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú torí pé àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti ti Jòhánù jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn tó bá sin Jèhófà àti Jésù máa là á já nígbà ìpọ́njú ńlá. Dáníẹ́lì sọ pé orúkọ àwọn tó máa là á já máa “wà nínú ìwé.” Kí la lè ṣe kí orúkọ wa lè wà nínú ìwé náà? A gbọ́dọ̀ fi hàn láìsí tàbí ṣùgbọ́n pé a nígbàgbọ́ nínú Jésù tó jẹ́ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run. (Jòh. 1:29) A gbọ́dọ̀ ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà ká sì ṣèrìbọmi. (1 Pét. 3:21) Bákan náà, ó ṣe pàtàkì ká máa kọ́ àwọn míì nípa Jèhófà ká lè fi hàn pé à ń ti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn. Ìsinsìnyí ló yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì fọkàn tán ètò rẹ̀ pátápátá. Ìsinsìnyí ló yẹ ká ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá là á já nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá pa ọba àríwá àti ọba gúúsù run. w20.05 16 ¶18-19
Monday, June 6
Jèhófà, orúkọ rẹ wà títí láé.—Sm. 135:13.
Ádámù àti Éfà mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì tún mọ àwọn nǹkan pàtàkì míì nípa rẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé òun ni Ẹlẹ́dàá àwọn, Òun ló jẹ́ kí àwọn wà láàyè, òun ló fún àwọn ní Párádísè ẹlẹ́wà táwọn ń gbé tó sì mú kí àwọn di tọkọtaya. (Jẹ́n. 1:26-28; 2:18) Pẹ̀lú bí Jèhófà ṣe fún Ádámù àti Éfà ní ọpọlọ pípé, ǹjẹ́ wọ́n máa ronú jinlẹ̀ nípa gbogbo nǹkan tí Jèhófà ṣe fún wọn? Ṣéyẹn máa mú kí wọ́n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó fún wọn láwọn ẹ̀bùn náà, ṣé wọ́n á sì mọyì rẹ̀? Ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí túbọ̀ ṣe kedere nígbà tẹ́nì kan tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run wá sọ́dọ̀ wọn tó sì dán wọn wò. Sátánì fi ejò bojú ó sì béèrè lọ́wọ́ Éfà pé: “Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso gbogbo igi inú ọgbà?” (Jẹ́n. 2:16, 17; 3:1) Téèyàn bá wo ìbéèrè yẹn, á mọ̀ pé irọ́ wà ńbẹ̀, àfi bíi májèlé tẹ́nì kan rọra bù sínú oúnjẹ aládùn kan. Ohun tí Ọlọ́run sọ gan-an ni pé wọ́n lè jẹ èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà náà àyàfi ẹyọ kan péré. (Jẹ́n. 2:9) Bó ti wù kó rí, ṣe ni Sátánì yí ọ̀rọ̀ Jèhófà po. Ohun tí Sátánì sọ mú kó dà bíi pé Jèhófà kì í ṣe ọ̀làwọ́. Èyí lè mú kí Éfà ronú pé, ‘Ṣé kì í ṣe pé Ọlọ́run ń fi ohun kan dù wá?’ w20.06 3-4 ¶8-9
Tuesday, June 7
Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà.—Kól. 3:13.
Ohun tẹ́nì kan ṣe ló mú káwọn míì fà sẹ́yìn nínú ìjọ. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan ní “ìdí láti fẹ̀sùn kan” ẹlòmíì nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè rẹ́ wa jẹ. Tá ò bá sì kíyè sára, a lè di irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ àá bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fáwọn ará. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n parọ́ mọ́ Arákùnrin Pablo tó ń gbé ní South America pé ó hùwà àìtọ́, ìyẹn sì mú kó pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ní. Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀? Arákùnrin Pablo sọ pé: “Inú bí mi burúkú burúkú ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé jẹ. Kí n tó mọ̀, mi ò lọ sípàdé mọ́.” Ẹ̀rí ọkàn lè máa da ẹnì kan láàmú torí pé ó rú òfin Ọlọ́run nígbà kan rí, ó sì lè ronú pé Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ òun mọ́. Kódà lẹ́yìn tó ti ronú pìwà dà tí wọ́n sì fàánú hàn sí i, ó ṣì lè máa ronú pé òun ò yẹ lẹ́ni tó ń sin Jèhófà. Báwo lọ̀rọ̀ àwọn ará tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí ṣe rí lára rẹ? w20.06 19 ¶6-7
Wednesday, June 8
Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́.—Òwe 22:3.
Ó yẹ ká fòye mọ àwọn nǹkan tó lè wu wá léwu, ká sì mọ bá a ṣe máa yẹra fún un. (Héb. 5:14) Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká máa fọgbọ́n yan irú eré ìnàjú tá a máa ṣe àtàwọn nǹkan tá a fi ń gbafẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn eré tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ ni wọ́n máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n àtàwọn fíìmù. A mọ̀ pé Jèhófà kórìíra ìṣekúṣe àti pé ìṣekúṣe máa ń ṣàkóbá fáwọn tó ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀. Torí náà, a gbọ́dọ̀ yẹra fún gbogbo eré ìnàjú tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ láìfura. (Éfé. 5:5, 6) A gbọ́dọ̀ fòye mọ ewu tó wà nínú àwọn ìtàn èké táwọn apẹ̀yìndà ń tàn kálẹ̀. Wọ́n máa ń sọ ohun tí kò jóòótọ́ nípa àwọn ará wa tàbí nípa ètò Jèhófà ká lè máa ṣiyèméjì. (1 Tím. 4:1, 7; 2 Tím. 2:16) Irú àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ lè jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀. Torí náà, ká má ṣe tẹ́tí sáwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ tàbí gbà wọ́n gbọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé “àwọn èèyàn tí ìrònú wọn ti dìbàjẹ́, tí wọn ò mọ òtítọ́” ló máa ń tan irú àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ kálẹ̀. Ohun tí wọ́n ń fẹ́ ni pé ká máa bá àwọn ‘jiyàn ká sì máa bá wọn fa ọ̀rọ̀.’ (1 Tím. 6:4, 5) Wọ́n fẹ́ ká gba ohun táwọn ń sọ gbọ́ ká sì bẹ̀rẹ̀ sí í fura sáwọn ará wa. w20.09 29 ¶13, 15
Thursday, June 9
Máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara [rẹ].—1 Kọ́r. 10:24.
Ó yẹ kí tọkọtaya nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. (Éfé. 5:33) Bíbélì sọ pé ká máa fún àwọn míì ní nǹkan dípò ká máa wá bá a ṣe máa gba tọwọ́ wọn. (Ìṣe 20:35) Kí ló máa jẹ́ kí tọkọtaya nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn? Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ti mú kí ọ̀pọ̀ tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni túbọ̀ láyọ̀ nínú ìgbéyàwó wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ kan tó ń jẹ́ Steven sọ pé: “Tẹ́ ẹ bá ṣera yín lọ́kan, ẹ̀ẹ́ jọ mọ bẹ́ ẹ ṣe lè yanjú ìṣòro tó bá yọjú. Dípò kó o máa ronú pé ‘kí ló máa múnú mi dùn?’ Ṣe ni kó o ronú pé ‘kí ló máa múnú wa dùn?’ ” Bó ṣe rí lára Stephanie ìyàwó ẹ̀ náà nìyẹn, ó sọ pé: “Kò sẹ́ni tó fẹ́ máa bá oníjà gbélé. Tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín wa, a máa ń sapá láti mọ ohun tí ìṣòro náà jẹ́ gan-an. Lẹ́yìn náà, àá gbàdúrà, àá ṣèwádìí nínú ìwé ètò Ọlọ́run, àá sì jọ sọ ọ́ yanjú. Dípò ká bára wa jà, ìṣòro yẹn la máa ń yanjú.” Tí ọkọ tàbí aya kan bá ń ro tẹnì kejì rẹ̀ mọ́ tiẹ̀, inú àwọn méjèèjì máa dùn. w20.07 3-4 ¶5-6
Friday, June 10
Mò ń tẹ̀ síwájú nínú Ìsìn Àwọn Júù ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ lórílẹ̀-èdè mi.—Gál. 1:14.
Ká má ṣe gbára lé ara wa bá a ṣe ń sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kàwé dójú àmì, àní Gàmálíẹ́lì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ Júù táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún ló kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. (Ìṣe 5:34; 22:3) Kódà, ó tẹ̀ síwájú débi pé ó di ọ̀kan lára àwọn abẹnugan láàárín àwọn Júù. (Ìṣe 26:4) Pẹ̀lú gbogbo ohun tá a sọ yìí, Pọ́ọ̀lù ò gbára lé ara rẹ̀. Kí Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn èèyàn kà sí pàtàkì, àmọ́ tayọ̀tayọ̀ ló fi yááfì wọn. (Fílí. 3:8; àlàyé ìsàlẹ̀.) Àmọ́ ojú Pọ́ọ̀lù rí màbo torí pé ó di ọmọlẹ́yìn Jésù. Kódà, àwọn Júù bíi tiẹ̀ kórìíra rẹ̀ tìkà-tẹ̀gbin. (Ìṣe 23:12-14) Yàtọ̀ síyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ni, àwọn aláṣẹ Róòmù lù ú, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. (Ìṣe 16:19-24, 37) Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Pọ́ọ̀lù máa ń fẹ́ ṣe ohun tó dáa àmọ́ tí kò rọrùn fún un. (Róòmù 7:21-25) Láìfi gbogbo ìyẹn pè, Pọ́ọ̀lù fi ìtara ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, ó sì ń “láyọ̀ nínú àìlera” rẹ̀. Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún un? Ìdí ni pé ó túbọ̀ máa ń rí agbára Ọlọ́run láyé ẹ̀ láwọn ìgbà tí nǹkan bá nira fún un.—2 Kọ́r. 4:7; 12:10. w20.07 16 ¶7-8
Saturday, June 11
Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi . . . máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ.—Jòh. 14:12.
Ọwọ́ pàtàkì ló yẹ ká fi mú iṣẹ́ ìwàásù náà lónìí. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù náà máa gbòòrò gan-an, ọ̀pọ̀ ọdún la sì máa fi ṣe é lẹ́yìn tóun bá kú. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó jẹ́ káwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ rí ẹja pa lọ́nà ìyanu. Jésù wá fi àsìkò yẹn sọ fún wọn pé iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe pàtàkì ju iṣẹ́ èyíkéyìí míì lọ. (Jòh. 21:15-17) Nígbà tó kù díẹ̀ kó gòkè lọ sọ́run, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù náà máa kọjá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, kódà á dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé. (Ìṣe 1:6-8) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jésù fi ìran kan han àpọ́sítélì Jòhánù nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ “ní ọjọ́ Olúwa.” Jòhánù rí áńgẹ́lì tó ń darí àwọn tó ń wàásù “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” fún “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn.” (Ìfi. 1:10; 14:6) Kò sí àní-àní pé Jèhófà fẹ́ ká ṣiṣẹ́ ìwàásù náà ní kíkún títí dìgbà tó fi máa parí. w20.09 9 ¶5
Sunday, June 12
Nígbà tí a dán Ábúráhámù wò, ká kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán torí ìgbàgbọ́.—Héb. 11:17.
Nǹkan ò rọrùn nínú ìdílé Ábúráhámù torí pé Sérà ìyàwó rẹ̀ kò rọ́mọ bí. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi ń retí tí wọn ò gbọ́ pá tí wọn ò sì gbọ́ po. Nígbà tó yá, Sérà fún ọkọ rẹ̀ ní Hágárì ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ kó lè bímọ fún wọn. Àmọ́ gbàrà tí Hágárì lóyún Íṣímáẹ́lì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pẹ̀gàn Sérà. Ọ̀rọ̀ náà le débi pé ṣe ni Sérà lé Hágárì kúrò nílé. (Jẹ́n. 16:1-6) Nígbà tó yá Sérà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí Ábúráhámù pè ní Ísákì. Ábúráhámù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì yìí. Àmọ́ torí pé Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́, Ábúráhámù ní láti lé òun àti ìyá rẹ̀ kúrò nílé. (Jẹ́n. 21:9-14) Nígbà tó yá, Jèhófà tún ní kí Ábúráhámù fi Ísákì rúbọ. (Jẹ́n. 22:1, 2; Héb. 11:17-19) Nínú ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí, Ábúráhámù ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa mú àwọn ìlérí tó ṣe nípa àwọn ọmọ náà ṣẹ. w20.08 4 ¶9-10
Monday, June 13
Ẹ sì gbé ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.—Éfé. 4:24.
Ẹ wo bí inú àwọn tó jíǹde ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ìwà àtijọ́ wọn tì, tí wọ́n sì ń fi ìlànà Jèhófà sílò. Àwọn tó bá ṣe àwọn àyípadà yìí máa rí àjíǹde sí ìyè. Àmọ́ Jèhófà ò ní fàyè gba àwọn tó bá ṣọ̀tẹ̀ láti máa wà láàyè nìṣó nínú Párádísè. (Àìsá. 65:20; Jòh. 5:28, 29) Nínú ayé tuntun, gbogbo èèyàn máa rí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 10:22 tó sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa mú káwọn èèyàn Ọlọ́run dẹni tẹ̀mí ní ti pé wọ́n á túbọ̀ máa hùwà bíi ti Kristi bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ ìjẹ́pípé. (Jòh. 13:15-17; Éfé. 4:23) Ojoojúmọ́ ni ara wọn á máa jí pépé sí i tí wọ́n á sì máa sunwọ̀n sí i. Ẹ wo bí ìgbésí ayé ṣe máa dùn tó nígbà yẹn!—Jóòbù 33:25. w20.08 17 ¶11-12
Tuesday, June 14
‘Ẹ fi ṣe àfojúsùn yín láti má ṣe yọjú sí ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀’.—1 Tẹs. 4:11.
Ó yẹ ká máa fi sọ́kàn pé ṣe làwọn ará kan dìídì pinnu pé àwọn ò ní ṣègbéyàwó. Ó wu àwọn míì kí wọ́n ṣègbéyàwó àmọ́ wọn ò kàn tíì rí ẹni tí wọ́n máa fẹ́ ni. Nígbà tó jẹ́ pé ọkọ tàbí aya àwọn kan ti kú. Èyí ó wù ó jẹ́, ṣó yẹ káwọn tó wà nínú ìjọ máa lọ́ àwọn ará yìí nífun pé kí nìdí tí wọn ò fi tíì ṣègbéyàwó tàbí ṣó yẹ kí wọ́n máa sọ fún wọn pé àwọn á bá wọn wá ọkọ tàbí aya? Tí wọn ò bá bẹ̀ wá níṣẹ́, báwo ló ṣe máa rí lára wọn tá a bá lọ ń bá wọn wá ọkọ tàbí aya? (1 Tím. 5:13) Inú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó máa dùn tá a bá mọyì wọn torí ànímọ́ dáadáa tí wọ́n ní, tá ò sì káàánú wọn torí pé wọn ò tíì ṣègbéyàwó. Dípò ká máa káàánú wọn, ẹ jẹ́ ká mọyì wọn, ká sì máa yìn wọ́n torí pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ará wa yìí ò ní máa rò pé ohun tá à ń sọ fún wọn ni pé: “Mi ò nílò rẹ.” (1 Kọ́r. 12:21) Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n á mọ̀ pé a mọyì àwọn, inú wọn á sì dùn pé àwọn wúlò nínú ìjọ. w20.08 29 ¶10, 14
Wednesday, June 15
[Kristi] fara han èyí tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.—1 Kọ́r. 15:6.
Nígbà tó yá, Jésù fara han àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnra ẹ̀. (1 Kọ́r. 15:8) Ojú ọ̀nà Damásíkù ni Pọ́ọ̀lù tá a mọ̀ sí Sọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ wà nígbà tó gbọ́ ohùn Jésù tó ti jíǹde, ó sì tún rí Jésù nínú ìran pé ó wà lọ́run. (Ìṣe 9:3-5) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù yìí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jésù jíǹde lóòótọ́. (Ìṣe 26:12-15) Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù máa wọ àwọn kan lọ́kàn gan-an torí pé ṣáájú ìgbà yẹn, ó máa ń ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni. Lẹ́yìn tó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jésù ti jíǹde, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe káwọn míì lè gbà pé Jésù ti jíǹde. Wọ́n lù ú, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n, ọkọ̀ tó wọ̀ sì rì bó ṣe ń wàásù kiri pé Jésù kú, ó sì ti jíǹde. (1 Kọ́r. 15:9-11; 2 Kọ́r. 11:23-27) Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jésù jíǹde débi pé ó ṣe tán láti kú torí ohun tó gbà gbọ́. Bí àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe jẹ́rìí sí i pé Jésù jíǹde mú kó túbọ̀ dá àwa náà lójú pé Jésù jíǹde, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ǹjẹ́ ìyẹn ò mú kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé àjíǹde máa wáyé? w20.12 3 ¶8-10
Thursday, June 16
‘Tí ẹ bá wá Jèhófà, á jẹ́ kí ẹ rí òun.’—2 Kíró. 15:2.
Ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé mo máa ń lọ sípàdé déédéé?’ Láwọn ìpàdé wa, a máa ń rí okun gbà ká lè máa sin Jèhófà nìṣó, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin sì máa ń gbé wa ró. (Mát. 11:28) A tún lè bi ara wa pé, ‘Ṣé mo máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé?’ Tó o bá ń gbé pẹ̀lú ìdílé rẹ, ṣé ẹ máa ń ṣe ìjọsìn ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? Tó bá sì jẹ́ pé ṣe lò ń dágbé, ṣé o máa ń ṣètò àkókò láti fi kẹ́kọ̀ọ́ bíi pé o wà pẹ̀lú ìdílé rẹ? Bákan náà, ṣé o máa ń wàásù déédéé tó o sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́? Kí nìdí tó fi yẹ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí? Bíbélì sọ pé Jèhófà ń kíyè sí ohun tó wà lọ́kàn wa àtohun tá à ń rò, ó sì yẹ káwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Kíró. 28:9) Tá a bá rí i pé ó yẹ ká ṣe àwọn àyípadà kan nínú ohun tá à ń lé, ohun tá à ń rò àtàwọn nǹkan tá à ń ṣe, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣàtúnṣe. Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká múra sílẹ̀ de àwọn àdánwò tá a máa tó kojú. w20.09 19 ¶19-20
Friday, June 17
Ìkankan nínú yín tí kò bá sọ pé ó dìgbòóṣe sí gbogbo ohun ìní rẹ̀, kò lè di ọmọ ẹ̀yìn mi.—Lúùkù 14:33.
Jésù ṣe àkàwé nípa béèyàn ṣe lè di ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó fẹ́ kọ́ ilé gogoro àti ọba kan tó fẹ́ lọ jagun. Jésù sọ pé ẹni tó fẹ́ kọ́ ilé náà máa “kọ́kọ́ jókòó, kó ṣírò ohun tó máa ná an” bóyá òun á lè parí ẹ̀. Ọba náà sì gbọ́dọ̀ “kọ́kọ́ jókòó, kó sì gba ìmọ̀ràn” bóyá òun àtàwọn ọmọ ogun òun á lè kojú àwọn tí wọ́n fẹ́ lọ bá jà. (Lúùkù 14:27-32) Lọ́nà kan náà, Jésù mọ̀ pé ẹni tó bá máa di ọmọ ẹ̀yìn òun gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ronú ohun tó máa ná an. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwa tá à ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀. Ó ṣe pàtàkì ká ronú nípa bá a ṣe máa ṣàlàyé lọ́nà tó máa wọ akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́kàn táá sì fi ohun tó ń kọ́ sílò.—Neh. 8:8; Òwe 15:28a. w20.10 7 ¶5; 8 ¶7
Saturday, June 18
Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.—Mát. 28:19, 20.
Àwọn ìtọ́ni tí Jésù fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ṣe kedere. A gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn èèyàn lóhun tó pa láṣẹ. Àmọ́, kókó pàtàkì kan wà tá ò gbọ́dọ̀ gbójú fò nínú ìtọ́ni yẹn. Jésù ò sọ pé: ‘Ẹ máa kọ́ wọn ní gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín.’ Kàkà bẹ́ẹ̀ ó sọ pé, ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n “máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.” Tá a bá máa fi ìtọ́ni pàtó yìí sílò, kì í ṣe pé ká kàn máa kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa nìkan, ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa tọ́ wọn sọ́nà. (Ìṣe 8:31) Nígbà tí Jésù sọ pé ká “pa” àṣẹ òun mọ́, ohun tó ń sọ ni pé ká máa ṣègbọràn sí òun. Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe là ń kọ́ wọn láwọn ìlànà Ọlọ́run. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè máa fi àwọn ìlànà yẹn sílò nígbèésí ayé wọn lójoojúmọ́. (Jòh. 14:15; 1 Jòh. 2:3) A lè lo àpẹẹrẹ tiwa láti jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nílé ìwé, níbi iṣẹ́ tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré ìnàjú. Tá a bá wà pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, a lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó máa fi ẹ̀mí ẹ̀ tọ́ wọn sọ́nà.—Jòh. 16:13. w20.11 2-3 ¶3-5
Sunday, June 19
“Kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun tàbí nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.—Sek. 4:6.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kojú àwọn ìṣòro kan. Bí àpẹẹrẹ, ìwọ̀nba ni ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ní, wọn ò sì ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ bá a ṣe ní in lónìí. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ní láti wàásù fún àwọn èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè. Láìka gbogbo ìyẹn sí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn lo ìtara, wọ́n sì ṣe àṣeyọrí tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ní nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún péré, wọ́n ti wàásù ìhìn rere “láàárín gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.” (Kól. 1:6, 23) Lóde òní, Jèhófà ṣì ń darí àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ń fún wọn lágbára láti ṣe ohun tó fẹ́. Ó sábà máa ń darí wọn nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ṣe tán ẹ̀mí mímọ́ ló fi darí àwọn tó kọ ọ́. Inú Bíbélì la ti rí bí Jésù ṣe wàásù àti àṣẹ tó pa pé ká máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ. (Mát. 28:19, 20) Jèhófà Ọlọ́run wa kì í ṣe ojúsàájú, ó sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa wàásù ìhìn rere yìí “fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn.” (Ìfi. 14:6, 7) Ó dájú pé gbogbo èèyàn ni Jèhófà fẹ́ kó gbọ́ ìhìn rere. w20.10 21 ¶6-8
Monday, June 20
Ò ń gba àwọn ẹni rírẹlẹ̀ là, ṣùgbọ́n o kì í fi ojú rere wo àwọn agbéraga.—2 Sám. 22:28.
Ọba Dáfídì nífẹ̀ẹ́ “òfin Jèhófà.” (Sm. 1:1-3) Bákan náà, Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà máa ń gba àwọn onírẹ̀lẹ̀ là àmọ́ ó kórìíra àwọn agbéraga. Torí náà, Dáfídì jẹ́ kí òfin Jèhófà tọ́ òun sọ́nà, ó sì tún èrò ẹ̀ ṣe. Ó sọ pé: “Màá yin Jèhófà, ẹni tó fún mi ní ìmọ̀ràn. Kódà láàárín òru, èrò inú mi ń tọ́ mi sọ́nà.” (Sm. 16:7) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a máa jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún èrò wa ṣe ká má bàa ṣìwà hù. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa dà bí ohùn tó ń sọ fún wa pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” Á sì kìlọ̀ fún wa tá a bá fẹ́ yà bàrá yálà sí ọ̀tún tàbí sí òsì. (Àìsá. 30:21) Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà. (Àìsá. 48:17) Bí àpẹẹrẹ, tá ò bá ṣègbọràn sí Jèhófà, ó lè di dandan kí ẹlòmíì bá wa wí, ìyẹn sì lè kó ìtìjú bá wa. Àǹfààní míì ni pé àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà torí a mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa bí bàbá ṣe ń nífẹ̀ẹ́ ọmọ.—Héb. 12:7. w20.11 20 ¶6-7
Tuesday, June 21
Nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa àjíǹde àwọn òkú, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe yẹ̀yẹ́.—Ìṣe 17:32.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èrò yìí ló mú káwọn kan nílùú Kọ́ríńtì gbà pé kò sí àjíǹde. (1 Kọ́r. 15:12) Àwọn míì ronú pé èdè ìṣàpẹẹrẹ ni Bíbélì lò nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde ní ti pé wọ́n “kú” torí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì “wá sí ìyè” nígbà tí wọ́n di Kristẹni. Ohun yòówù kó fà á tí wọ́n fi ronú bẹ́ẹ̀, asán ni ìgbàgbọ́ wọn tí wọn ò bá gbà pé àjíǹde wà. Tí Ọlọ́run ò bá jí Jésù dìde, á jẹ́ pé kò sí ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa nìyẹn, a ò sì lè rí ìdáríjì gbà. Torí náà, àwọn tí kò gbà pé àjíǹde wà kò ní ìrètí kankan. (1 Kọ́r. 15:13-19; Héb. 9:12, 14) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnra ẹ̀ mọ̀ pé Ọlọ́run “ti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú.” Àjíǹde Jésù sàn ju àwọn àjíǹde tó ti wáyé ṣáájú tiẹ̀ torí pé àwọn ẹni yẹn tún pa dà kú lẹ́yìn tí wọ́n jí wọn dìde. Pọ́ọ̀lù sọ pé Jésù ni “àkọ́so nínú àwọn tó ti sùn nínú ikú.” Òun lẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run jí dìde ní ẹ̀dá ẹ̀mí, òun náà sì lẹni àkọ́kọ́ tó lọ sí ọ̀run lẹ́yìn tó jíǹde.—1 Kọ́r. 15:20; Ìṣe 26:23; 1 Pét. 3:18, 22. w20.12 5 ¶11-12
Wednesday, June 22
Wọ́n ń fi àwọn àṣẹ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà . . . ti pinnu lé lórí jíṣẹ́ fún wọn kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́.—Ìṣe 16:4.
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ìgbìmọ̀ olùdarí tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ìṣe 2:42) Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn kan ń jiyàn lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ ní nǹkan bí ọdún 49 S.K., ẹ̀mí mímọ́ darí ìgbìmọ̀ olùdarí láti dórí ìpinnu tó ṣe gbogbo ìjọ láǹfààní. Ká sọ pé wọ́n jẹ́ kọ́rọ̀ yìí dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn ará ni, iṣẹ́ ìwàásù náà ì bá ti dúró. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Júù làwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà, wọn ò jẹ́ kí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù ràn wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò fàyè gba èrò àwọn tó ń gbé àṣà náà lárugẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ni wọ́n gbára lé láti tọ́ wọn sọ́nà. (Ìṣe 15:1, 2, 5-20, 28) Kí nìyẹn wá yọrí sí? Jèhófà bù kún ìpinnu tí wọ́n ṣe, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀ nínú ìjọ, iṣẹ́ ìwàásù náà sì tẹ̀ síwájú. (Ìṣe 15:30, 31; 16:5) Ètò Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà. w20.10 22-23 ¶11-12
Thursday, June 23
Sólómọ́nì ọmọ mi, [ni] ẹni tí Ọlọ́run yàn.—1 Kíró. 29:1.
A lè má ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan bóyá nítorí ọjọ́ orí wa, ìlera wa tàbí àwọn nǹkan míì. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Ọba Dáfídì. Ó wu Dáfídì gan-an pé kó kọ́ tẹ́ńpìlì fún Jèhófà. Àmọ́ nígbà tí wọ́n sọ fún un pé òun kọ́ ló máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà, kò rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló kọ́wọ́ ti ẹni tí Jèhófà yàn. Kódà, ọ̀pọ̀ wúrà àti fàdákà ló fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà. Àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fún wa. (2 Sám. 7:12, 13; 1 Kíró. 29:3-5) Àìsàn tó ń ṣe Arákùnrin Hugues lórílẹ̀-èdè Faransé ló mú kó fi iṣẹ́ alàgbà sílẹ̀. Kódà, ó ṣòro fún un gan-an láti ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé. Ó sọ pé: “Níbẹ̀rẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì mú mi, mo sì ronú pé mi ò wúlò. Àmọ́ nígbà tó yá, mo wá rí i pé á dáa kí n mohun tí agbára mi gbé, ìyẹn sì jẹ́ kí n máa láyọ̀ bí mo ti ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Torí náà, mo pinnu pé mi ò ní bọ́hùn bíi ti Gídíónì àtàwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu, wọn ò juwọ́ sílẹ̀.”—Oníd. 8:4. w20.12 25 ¶14-15
Friday, June 24
Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa.—1 Jòh. 4:7.
Nínú àkọsílẹ̀ Jòhánù nípa ìgbésí ayé Jésù, ó lo ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” àti “nífẹ̀ẹ́” ju iye ìgbà tí àpapọ̀ àwọn Ìwé Ìhìn Rere mẹ́ta tó kù lò ó. Àwọn ìwé tó kọ jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́ ló gbọ́dọ̀ máa mú ká ṣe gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. (1 Jòh. 4:10, 11) Àmọ́ ó ṣe díẹ̀ kí Jòhánù fúnra ẹ̀ tó kọ́ ẹ̀kọ́ yìí. Nígbà tí Jòhánù wà pẹ̀lú Jésù, àwọn ìgbà kan wà tí kò fìfẹ́ hàn. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì gba Samáríà kọjá. Nígbà tí wọ́n dé abúlé kan ní Samáríà, àwọn èèyàn ibẹ̀ ò tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Jòhánù wá sọ fún Jésù pé kó jẹ́ káwọn pe iná wá látọ̀run, kó sì pa gbogbo àwọn ará ìlú náà run! (Lúùkù 9:52-56) Ìgbà kan tún wà tí Jòhánù àti Jémíìsì arákùnrin rẹ̀ lọ bá ìyá wọn pé kó bá àwọn bẹ Jésù kó lè fún àwọn ní ipò pàtàkì nínú Ìjọba rẹ̀. Nígbà táwọn àpọ́sítélì tó kù gbọ́ ohun tí Jémíìsì àti Jòhánù ṣe, inú bí wọn gan-an! (Mát. 20:20, 21, 24) Síbẹ̀, láìka gbogbo kùdìẹ̀-kudiẹ Jòhánù sí, Jésù ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Jòh. 21:7. w21.01 8-9 ¶3-4
Saturday, June 25
Kristi pàápàá kò ṣe ohun tó wù ú.—Róòmù 15:3.
Ìpinnu tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní ni Jèhófà máa ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kì í ṣe torí àǹfààní ara ẹ̀ ni Jèhófà ṣe dá àwọn nǹkan lọ́run àti láyé, bí kò ṣe torí àǹfààní àwọn míì. Kò sẹ́ni tó fipá mú un pé kó fi ọmọ rẹ̀ rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fínúfíndọ̀ yọ̀ǹda ẹ̀ ká lè rí ìyè. Ìpinnu tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní ni Jésù náà máa ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó rẹ̀ ẹ́ tó sì fẹ́ sinmi, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Máàkù 6:31-34) Olórí ìdílé kan mọ̀ pé, ó ṣe pàtàkì kóun ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu tó sì máa ṣe ìdílé òun láǹfààní, kì í sì í fi ọwọ́ kékeré mú ojúṣe náà. Kì í ṣèpinnu torí bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń ronú jinlẹ̀ dáadáa, ó sì máa ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà. (Òwe 2:6, 7) Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe tara ẹ̀ nìkan ló máa rò tó bá fẹ́ ṣèpinnu, á ronú nípa bó ṣe máa ṣe àwọn míì láǹfààní. (Fílí. 2:4) Bí ọkọ kan bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù, ó máa ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. w21.02 7 ¶19-21
Sunday, June 26
Ásà ṣe ohun tó dára tó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.—2 Kíró. 14:2.
Nígbà tí Ọba Ásà wà lọ́dọ̀ọ́, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì nígboyà. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Ábíjà bàbá rẹ̀ kú, Ásà di ọba, ó sì gbógun ti ìbọ̀rìṣà. Ó tún sọ fáwọn èèyàn ilẹ̀ “Júdà pé kí wọ́n wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, kí wọ́n sì máa pa Òfin àti àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (2 Kíró. 14:1-7) Nígbà tí Síírà ará Etiópíà wá gbéjà kò wọ́n pẹ̀lú ọmọ ogun mílíọ̀nù kan, Ásà ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu, ó bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, ó ní: “Jèhófà, kò jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ bóyá àwọn tí o fẹ́ ràn lọ́wọ́ pọ̀ tàbí wọn ò lágbára. Ràn wá lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.” Àdúrà tí Ásà gbà yìí jẹ́ ká rí bó ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó, tó sì dá a lójú pé Jèhófà lágbára láti dá òun àtàwọn èèyàn ẹ̀ nídè. Ásà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, “Jèhófà [sì] ṣẹ́gun àwọn ará Etiópíà.” (2 Kíró. 14:8-12) Ìwọ náà máa gbà pé ẹ̀rù máa ba Ásà gan-an nígbà táwọn ọmọ ogun mílíọ̀nù kan wá gbéjà kò ó. Síbẹ̀, torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó ṣẹ́gun wọn. w21.03 5 ¶12-13
Monday, June 27
Ẹ ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín.—Róòmù 12:10.
Bíbélì sọ nípa àwọn èèyàn aláìpé tí wọ́n fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sáwọn míì. Àpẹẹrẹ kan ni ti Jónátánì àti Dáfídì. Bíbélì sọ pé: “Jónátánì àti Dáfídì wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, Jónátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ara rẹ̀.” (1 Sám. 18:1) Dáfídì ni Jèhófà yàn láti jọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Ìyẹn wá mú kí Sọ́ọ̀lù máa jowú Dáfídì, ó sì ń wọ́nà àtipa á. Àmọ́, Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù ò fara mọ́ ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ ṣe yìí, torí náà kò dara pọ̀ mọ́ ọn láti lépa Dáfídì. Kódà, ṣe ni Jónátánì àti Dáfídì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, wọ́n sì jọ ṣàdéhùn pé àwọn ò ní dalẹ̀ ara àwọn. (1 Sám. 20:42) Ìfẹ́ tó wà láàárín Jónátánì àti Dáfídì ṣàrà ọ̀tọ̀, pàápàá tá a bá ronú àwọn nǹkan tó lè mú kí Jónátánì pinnu pé òun ò ní bá Dáfídì ṣọ̀rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ni Jónátánì fi ju Dáfídì lọ, kódà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbà tó ọgbọ̀n (30) ọdún lọ́wọ́ rẹ̀. Jónátánì lè ronú pé òun ò lè bá Dáfídì ṣọ̀rẹ́ torí pé òun kì í ṣẹgbẹ́ ẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìrírí. Bó ti wù kó rí, Jónátánì ò fojú ọmọdé wo Dáfídì, kò sì kà á sí aláìní ìrírí. w21.01 21-22 ¶6-7
Tuesday, June 28
Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀.—Jém. 1:2.
Jésù ṣèlérí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọ́n máa láyọ̀, àmọ́ ó tún kìlọ̀ fún wọn pé wọ́n máa kojú àdánwò. (Mát. 10:22, 23; Lúùkù 6:20-23) Inú wa máa ń dùn gan-an pé a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, àmọ́ báwo ló ṣe máa rí lára wa tí àwọn tó wà nínú ìdílé wa bá ń ta kò wá, tí ìjọba ń ṣe inúnibíni sí wa, tí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọléèwé wa sì ń fúngun mọ́ wa pé ká ṣe ohun tí kò tọ́? Ká sòótọ́, irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kẹ́rù bà wá. Ọ̀pọ̀ ò gbà pé èèyàn lè láyọ̀ tó bá ń kojú inúnibíni. Àmọ́ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ká ṣe gan-an nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, Jémíìsì sọ pé dípò ká máa kọ́kàn sókè nítorí àwọn ìṣòro wa, ṣe ló yẹ ká máa láyọ̀. (Jém. 1:2, 12) Bákan náà, Jésù sọ pé ká máa láyọ̀ tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa. (Mát. 5:11) Jèhófà wá mí sí Jémíìsì láti kọ̀wé sáwọn Kristẹni kó sì fún wọn nímọ̀ràn táá jẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀ tí wọ́n bá tiẹ̀ ń kojú àdánwò. w21.02 26 ¶1-2; 27 ¶5
Wednesday, June 29
Yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán tó ń ba ohun mímọ́ jẹ́.—1 Tím. 6:20.
Àwọn Kristẹni kan nígbà ayé Tímótì kò mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wọn pé kí wọ́n máa bá òun ṣiṣẹ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Démà, Fíjẹ́lọ́sì, Hẹmojẹ́nísì, Híméníọ́sì, Alẹkisáńdà àti Fílétọ́sì. (1 Tím. 1:19, 20; 2 Tím. 1:15; 2:16-18; 4:10) Ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn yìí ti fìgbà kan rí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àmọ́ nígbà tó yá, wọn ò mọyì òtítọ́ mọ́. Kí ni Sátánì ń ṣe ká lè pàdánù àwọn ohun tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wa? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn. Ó ń lo eré ìnàjú, tẹlifíṣọ̀n, rédíò àtàwọn ìwé ìròyìn láti mú ká máa ronú ká sì máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí òtítọ́ bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Ó máa ń mú káwọn èèyàn fúngun mọ́ wa tàbí ṣenúnibíni sí wa ká lè dá iṣẹ́ ìwàásù dúró. Ó tún máa ń lo “àwọn ohun tí [àwọn apẹ̀yìndà] ń fi ẹ̀tàn pè ní ‘ìmọ̀’ ” ká lè fi òtítọ́ sílẹ̀. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi òtítọ́ sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀.—1 Tím. 6:21. w20.09 27 ¶6-8
Thursday, June 30
Jèhófà yóò gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ojú rere; Jèhófà yóò dáhùn àdúrà mi.—Sm. 6:9.
Ṣé ọ̀rẹ́ rẹ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ kan ti dalẹ̀ rẹ rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á dáa kó o ṣàyẹ̀wò ìtàn Ábúsálómù ọmọ Ọba Dáfídì. (2 Sám. 15:5-14, 31; 18:6-14) Bó o ṣe ń ronú nípa ìtàn náà, sọ ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ ṣe sí ẹ fún Jèhófà, kó o sì jẹ́ kó mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ. (Sm. 6:6-8) Lẹ́yìn náà, fojú inú wo bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe máa rí lára Dáfídì. Ó nífẹ̀ẹ́ Ábúsálómù, ó sì fọkàn tán Áhítófẹ́lì. Àmọ́, àwọn méjèèjì dalẹ̀ rẹ̀, kódà wọ́n gbìyànjú láti pa á. Ohun tí wọ́n ṣe yìí dun Dáfídì gan-an. Dáfídì lè ronú pé àwọn ọ̀rẹ́ òun tó kù ti dara pọ̀ mọ́ Ábúsálómù, kó má sì fọkàn tán wọn mọ́. Tó bá jẹ́ pé irú èrò tí Dáfídì ní nìyẹn, ó lè fẹ́ sá kúrò nílùú lóun nìkan, kó má sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀ lé òun. Ó tún lè ro ara ẹ̀ pin, kó sì gbà pé ó ti tán fún òun. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó ní káwọn ọ̀rẹ́ òun ran òun lọ́wọ́, ó sì gbé ìgbésẹ̀ láìjáfara lórí ìpinnu tó ṣe. Bákan náà, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì fọkàn tán àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. w21.03 15 ¶7-8; 17 ¶10-11