ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es22 ojú ìwé 67-77
  • July

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Friday, July 1
  • Saturday, July 2
  • Sunday, July 3
  • Monday, July 4
  • Tuesday, July 5
  • Wednesday, July 6
  • Thursday, July 7
  • Friday, July 8
  • Saturday, July 9
  • Sunday, July 10
  • Monday, July 11
  • Tuesday, July 12
  • Wednesday, July 13
  • Thursday, July 14
  • Friday, July 15
  • Saturday, July 16
  • Sunday, July 17
  • Monday, July 18
  • Tuesday, July 19
  • Wednesday, July 20
  • Thursday, July 21
  • Friday, July 22
  • Saturday, July 23
  • Sunday, July 24
  • Monday, July 25
  • Tuesday, July 26
  • Wednesday, July 27
  • Thursday, July 28
  • Friday, July 29
  • Saturday, July 30
  • Sunday, July 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
es22 ojú ìwé 67-77

July

Friday, July 1

Gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé la ti fún mi.​—Mát. 28:18.

A gbọ́dọ̀ di ọ̀rẹ́ Jésù kí Jèhófà tó lè dáhùn àdúrà wa. Èyí kọjá ká kàn sọ pé “ní orúkọ Jésù” níparí àdúrà wa. A gbọ́dọ̀ mọ bí Jèhófà ṣe ń lo Jésù láti dáhùn àdúrà wa. Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ohunkóhun tí ẹ bá béèrè ní orúkọ mi, màá ṣe é.” (Jòh. 14:13) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ló ń gbọ́ àdúrà wa, Jésù ló fún láṣẹ láti mú ìpinnu Òun ṣẹ. Kí Jèhófà tó dáhùn àdúrà wa, ó máa wò ó bóyá à ń fi ìmọ̀ràn Jésù sílò. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run náà máa dárí jì yín; àmọ́ tí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.” (Mát. 6:14, 15) Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà pé ká máa bá àwọn èèyàn lò bí Jèhófà àti Jésù ṣe ń bá wa lò! w20.04 22 ¶6

Saturday, July 2

Ìhìn rere ni à ń kéde fún yín, kí ẹ lè yí pa dà kúrò nínú àwọn ohun asán yìí sọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.​—Ìṣe 14:15.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ ohun táwọn èèyàn náà nífẹ̀ẹ́ sí, torí náà ó gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́nà táá fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn Lísírà tí Pọ́ọ̀lù bá sọ̀rọ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Ìwé Mímọ́. Torí náà Pọ́ọ̀lù bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tí wọ́n á fi tètè lóye ohun tó ń sọ. Ó sọ̀rọ̀ nípa bí irè oko ṣe ń jáde àti bí Ọlọ́run ṣe ń fi ayọ̀ kún ọkàn wọn. Ó lo àwọn ọ̀rọ̀ àtàwọn àpèjúwe tó máa tètè yé àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀. Lo òye kó o lè mọ ohun táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kó o wá nasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ lọ́nà tó bá a mu. Báwo lo ṣe lè mọ ohun tí ẹnì kan nífẹ̀ẹ́ sí kó o tó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀? Ṣe ni kó o kíyè sí ohun tó wà ní àyíká rẹ̀. O ò ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú ohun tí ẹni yẹn ń ṣe lọ́wọ́, bóyá ó ń tún ọgbà ẹ̀ ṣe tàbí ó ń kàwé lọ́wọ́, ó sì lè máa tún ọkọ̀ rẹ̀ ṣe tàbí kó máa ṣe nǹkan míì. (Jòh. 4:7) Kódà aṣọ tí ẹnì kan wọ̀ lè jẹ́ kó o mọ ibi tí ẹnì kan ti wá, iṣẹ́ tó ń ṣe tàbí irú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó nífẹ̀ẹ́ sí. w20.04 11 ¶11-12

Sunday, July 3

Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ [Ọlọ́run], torí ó ń bójú tó yín.​—1 Pét. 5:7.

Ìṣòro tàbí àníyàn táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kan ní tún yàtọ̀. Ìṣòro náà ni pé ara wọn kì í balẹ̀ tí wọ́n bá wà láàárín àwọn èèyàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń nira fún wọn tí wọ́n bá wà láàárín àwọn èèyàn, síbẹ̀ wọ́n máa ń wá sáwọn ìpàdé, àpéjọ àyíká àti ti agbègbè. Kì í rọrùn fún wọn láti bá ẹni tí wọn ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀, síbẹ̀ wọ́n máa ń lọ sóde ẹ̀rí, wọ́n sì ń wàásù fáwọn èèyàn. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ nìyẹn, máa rántí pé ó ti ṣe àwọn kan bẹ́ẹ̀ rí. Bákan náà, àwọn kan wà láàárín wa tí wọ́n ṣì ń bá irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ yí. Fi sọ́kàn pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀. Bó o ṣe ń bá a lọ láìbọ́hùn jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà ń tì ẹ́ lẹ́yìn àti pé òun ló ń fún ẹ lágbára tó o nílò. (Fílí. 4:6, 7) Bó o ṣe ń bá a lọ láti máa jọ́sìn Jèhófà láìka ti àìlera tàbí ẹ̀dùn ọkàn tó o ní sí, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé inú Jèhófà ń dùn sí ẹ. Ọ̀pọ̀ wa la ní àìlera tá à ń bá yí, síbẹ̀ à ń fara dà á. (2 Kọ́r. 4:16) Torí náà, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, gbogbo wa pátá la máa sá eré ìje ìyè yìí dópin! w20.04 31 ¶20-21

Monday, July 4

Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere . . . látinú àwọn ohun tó dá.​—Róòmù 1:20.

Tá a bá fara balẹ̀ wo bí Jèhófà ṣe dá ayé yìí, àá gbà pé ọgbọ́n rẹ̀ kò láfiwé. (Héb. 3:4) Ayé yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé òun nìkan ló ní gbogbo nǹkan tó ń gbẹ́mìí èèyàn ró. Ojú òfúrufú gbalasa ni ayé wa yìí wà bí ìgbà tí ọkọ̀ kan wà lójú agbami. Àmọ́ ìyàtọ̀ wà láàárín ayé wa yìí àti ọkọ̀ táwọn èèyàn kúnnú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ pé àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà ló máa pèsè afẹ́fẹ́ oxygen tí wọ́n á máa mí, àwọn ló máa gbin oúnjẹ tí wọ́n á máa jẹ, àwọn ló máa pèsè omi tí wọ́n á máa mu, tí kò sì sí ibi tí wọ́n á da ìgbọ̀nsẹ̀ àtàwọn ìdọ̀tí míì sí. Ọdún mélòó lẹ rò pé wọ́n á lè lò nínú ọkọ̀ náà? Ó ṣe kedere pé wọn ò ní pẹ́ kú. Lọ́wọ́ kejì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni àìlóǹkà èèyàn, àwọn ẹranko àtàwọn nǹkan míì ti ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yìí. Òun fúnra ẹ̀ ló ń pèsè afẹ́fẹ́ oxygen, oúnjẹ, omi àtàwọn nǹkan míì tó ń gbé ẹ̀mí wa ró, wọn ò sì dín kù látọjọ́ tí Ọlọ́run ti dá ayé yìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ayé yìí náà làwọn ìgbọ̀nsẹ̀ wa àtàwọn ìdọ̀tí míì wà, síbẹ̀ ayé yìí ṣì rẹwà, ó sì dùn ún gbé. Kí ló jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe? Ìdí ni pé ọ̀nà àgbàyanu kan wà tí ayé yìí gbà ń ṣe àtúnlò àwọn nǹkan tó ń gbẹ́mìí wa ró. w20.05 20 ¶3-4

Tuesday, July 5

Ó dájú pé ẹ ò ní kú.​—Jẹ́n. 3:4.

Sátánì kò pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ rárá. Ṣe ló kúkú ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́ ní tààràtà, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ pe Jèhófà ní òpùrọ́. Ohun tí Sátánì ṣe yìí ló mú kó di èṣù tàbí abanijẹ́. Èṣù tan Éfà jẹ pátápátá, Éfà sì gba ohun tó sọ gbọ́. (1 Tím. 2:14) Éfà fọkàn tán Sátánì dípò Jèhófà, ìyẹn sì mú kó ṣe ìpinnu tó burú jù lọ. Ó ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó sì tàpá sí àṣẹ rẹ̀. Ló bá jẹ èso tí Jèhófà ní wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ, nígbà tó yá ó fún Ádámù náà jẹ lára ẹ̀. (Jẹ́n. 3:6) Kí lo rò pé Éfà ì bá ti sọ fún Sátánì? Jẹ́ ká wò ó báyìí ná, ká ní Éfà sọ fún un pé: “Mi ò mọ̀ ẹ́, àmọ́ mo mọ Jèhófà Baba mi, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, mo sì gba ohun tó sọ gbọ́. Òun ló fún èmi àti ọkọ mi ní gbogbo ohun tá a ní. Kí lo fi ara ẹ pè ná, àyà mà kò ẹ́ o? Kó bó ti ń ṣe ẹ́ kúrò lọ́dọ̀ mi!” Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó pé ọmọbìnrin òun nífẹ̀ẹ́ òun dénú, kò sì gbàgbàkugbà láyè! (Òwe 27:11) Àmọ́ Éfà ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú, bọ́rọ̀ Ádámù náà sì ṣe rí nìyẹn. Torí pé Ádámù àti Éfà ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọn ò sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i, wọn ò gbèjà Jèhófà nígbà tí Sátánì ta kò ó. w20.06 4 ¶10-11

Wednesday, July 6

Àwọn obìnrin tó ń kéde ìhìn rere jẹ́ agbo ọmọ ogun ńlá.​—Sm. 68:11.

Ó yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn arábìnrin wa torí iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àwọn kan lára wọn ń kọ́ àwọn ilé tá à ń lò fún ìjọsìn, wọ́n sì ń tún wọn ṣe. Àwọn kan wà láwọn ìjọ tàbí àwùjọ tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè, àwọn kan sì ń yọ̀ǹda ara wọn ní Bẹ́tẹ́lì. Àwọn kan máa ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù, àwọn míì sì ń túmọ̀ ìtẹ̀jáde wa sáwọn èdè míì, nígbà táwọn kan jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí míṣọ́nnárì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìyàwó máa ń ran àwọn ọkọ wọn lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń bójú tó ojúṣe ńlá tí wọ́n ní nínú ìjọ àti nínú ètò Ọlọ́run. Torí pé àwọn obìnrin yìí ń ti àwọn ọkọ wọn lẹ́yìn, ó jẹ́ kó rọrùn fún àwọn arákùnrin yẹn láti fi hàn pé “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” làwọn. (Éfé. 4:8) Àwọn alàgbà tó gbọ́n mọ̀ pé “agbo ọmọ ogun ńlá” làwọn arábìnrin wa torí pé wọ́n wà lára àwọn tó ń fìtara wàásù ìhìn rere jù. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alàgbà mọ̀ pé iṣẹ́ ńlá làwọn àgbà obìnrin ń ṣe bí wọ́n ṣe ń ran àwọn ọ̀dọ́bìnrin lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro wọn. (Títù 2:3-5) Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ó yẹ ká mọyì àwọn arábìnrin wa, ká sì máa gbóríyìn fún wọn! w20.09 23-24 ¶13-14

Thursday, July 7

Kò wu Baba mi tó wà ní ọ̀run pé kí ọ̀kan péré nínú àwọn ẹni kékeré yìí ṣègbé.​—Mát. 18:14.

Jèhófà kì í gbàgbé àwọn tó ti fìgbà kan rí ṣe dáadáa tí wọ́n wá fà sẹ́yìn nígbà tó yá. Yàtọ̀ síyẹn, kò gbàgbé ohun tí wọ́n ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀. (Héb. 6:10) Wòlíì Àìsáyà lo àpèjúwe kan láti jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ tó. Ó ní: “Ó máa bójú tó agbo ẹran rẹ̀ bíi ti olùṣọ́ àgùntàn. Ó máa fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ, ó sì máa gbé wọn sí àyà rẹ̀.” (Àìsá. 40:11) Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá nígbà tí ọ̀kan lára àgùntàn rẹ̀ bá ṣáko lọ? Jésù jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà nígbà tó bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kí lèrò yín? Tí ọkùnrin kan bá ní ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, tí ọ̀kan nínú wọn sì sọ nù, ṣebí ó máa fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ lórí òkè ni, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá èyí tó sọ nù? Tó bá sì rí i, mò ń sọ fún yín, ó dájú pé ó máa yọ̀ gidigidi torí rẹ̀ ju mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) tí kò tíì sọ nù.”​—Mát. 18:12, 13. w20.06 19-20 ¶8-9

Friday, July 8

Tí ọkùnrin kan bá ń sapá láti di alábòójútó, iṣẹ́ rere ló fẹ́ ṣe.​—1 Tím. 3:1.

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń sin Jèhófà. (Sm. 27:4; 84:10) Ó dáa gan-an tí arákùnrin kan bá yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti ṣe púpọ̀ sí i nínú ètò Jèhófà. Àmọ́ tó bá wá ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ kan, kò yẹ kó ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. (Lúùkù 17:7-10) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kó sì ṣe tán láti ṣiṣẹ́ sin àwọn míì. (2 Kọ́r. 12:15) Àpẹẹrẹ àwọn tó ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ wà nínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, Díótíréfè fẹ́ fi ara rẹ̀ “ṣe olórí” nínú ìjọ, ìyẹn sì fi hàn pé kò mọ̀wọ̀n ara ẹ̀. (3 Jòh. 9) Ìgbéraga mú kí Ùsáyà ṣe ohun tí kò láṣẹ láti ṣe. (2 Kíró. 26:16-21) Ábúsálómù lo ọgbọ́n àrékérekè láti mú káwọn èèyàn gba tiẹ̀ torí pé ó fẹ́ di ọba. (2 Sám. 15:2-6) Àwọn àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé inú Jèhófà kì í dùn sáwọn tó bá ń wá ògo ara wọn. (Òwe 25:27) Bó pẹ́ bó yá, ìparun ló máa ń gbẹ̀yìn ìgbéraga.​—Òwe 16:18. w20.07 4 ¶7-8

Saturday, July 9

Kálukú ló máa ru ẹrù ara rẹ̀.​—Gál. 6:5.

Àwọn ìdílé Kristẹni kan ti ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì torí ogun tàbí torí kí wọ́n lè ríṣẹ́. Irú àwọn ọmọ ìdílé bẹ́ẹ̀ sábà máa ń lọ síléèwé tí wọ́n ti ń fi èdè tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè náà kọ́ wọn. Ó lè pọn dandan pé káwọn òbí náà kọ́ èdè yẹn kí wọ́n tó lè ríṣẹ́. Kí ni wọ́n máa ṣe tó bá jẹ́ pé ìjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn wà lórílẹ̀-èdè yẹn? Ìjọ wo ni ìdílé náà máa lọ? Ṣé ìjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn ni àbí èyí tó ń sọ èdè ibi tí wọ́n wà? Olórí ìdílé ló máa pinnu ìjọ tí ìdílé ẹ̀ máa lọ. Torí pé kò sẹ́ni tó máa báwọn ṣèpinnu yìí, ó gbọ́dọ̀ ronú nípa ohun tó máa ṣe ìdílé ẹ̀ láǹfààní jù. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣèpinnu, a gbọ́dọ̀ fara mọ́ ìpinnu èyíkéyìí tí olórí ìdílé náà bá ṣe, ká jẹ́ kára tù wọ́n, ká sì fi hàn pé a mọyì wọn àti pé wọ́n wúlò nínú ìjọ.​—Róòmù 15:7. w20.08 30 ¶17-18

Sunday, July 10

Ọlọ́run . . .  yan àwọn ohun aláìlera ayé.​—1 Kọ́r. 1:27.

Kò yẹ ká ronú pé àwọn tó jẹ́ alágbára, àwọn tó kàwé, tó lówó lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n wá láti ibi tó lórúkọ ló lè wúlò fún Jèhófà tí Jèhófà á sì fún lókun. Kì í ṣe àwọn nǹkan yìí ló máa jẹ́ ká wúlò fún Jèhófà. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń sin Jèhófà ló jẹ́ ‘ọlọ́gbọ́n nípa ti ara, alágbára tàbí tí wọ́n bí ní ilé ọlá,’ tí wọ́n bá tiẹ̀ wà, ìwọ̀nba ni. (1 Kọ́r. 1:26) Torí náà, tí o kò bá tiẹ̀ ní àwọn nǹkan tá a sọ lókè yìí, o ṣì lè sin Jèhófà. Bí nǹkan ṣe rí fún ẹ yìí ló máa mú kó o túbọ̀ rí ọwọ́ Jèhófà láyé ẹ. Bí àpẹẹrẹ, tí àyà ẹ bá ń já torí pé àwọn èèyàn ń ta kò ẹ́, ṣe ni kó o gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ nígboyà láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. (Éfé. 6:19, 20) Tó o bá ní àìsàn tó lágbára tàbí àwọn ìṣòro míì, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lókun kó o lè ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ gbé nínú ìjọsìn rẹ̀. Bó o bá ṣe ń rí ọwọ́ Jèhófà láyé ẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ máa lágbára. w20.07 16 ¶9

Monday, July 11

Ẹ máa wá Ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́.​—Mát. 6:33.

Tá a bá máa fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé wa, a gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan kan bíi ti Ábúráhámù. (Máàkù 10:28-30; Héb. 11:8-10) Má ronú pé o ò ní níṣòro torí pé ò ń sin Jèhófà. Àpẹẹrẹ Ábúráhámù fi hàn pé àwọn tó ń fi gbogbo ayé wọn sin Jèhófà náà máa ń níṣòro. (Jém. 1:2; 1 Pét. 5:9) Lónìí, ọ̀pọ̀ ìdí la ní tó fi yẹ ká tẹjú mọ́ èrè ọjọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ti jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé apá tó kẹ́yìn lára ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé yìí. Lára ìbùkún tá a máa gbádùn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run nígbà yẹn ni pé àwọn èèyàn wa tó ti kú máa jíǹde, àá sì rí wọn. Bákan náà, Jèhófà máa san Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ lẹ́san torí sùúrù àti ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nígbà tó bá jí wọn dìde. Ṣé wàá wà níbẹ̀ láti kí wọn káàbọ̀? Wàá wà níbẹ̀ tó o bá ń yááfì àwọn nǹkan torí Ìjọba Ọlọ́run bíi ti Ábúráhámù, tó ò ń fìtara sin Jèhófà nìṣó láìka àwọn ìṣòro tó ò ń kojú sí, tó o sì ń fi sùúrù dúró de Jèhófà.​—Míkà 7:7. w20.08 5-6 ¶13-14; 7 ¶17

Tuesday, July 12

Jẹ́ olóòótọ́, kódà títí dójú ikú, màá sì fún ọ ní adé ìyè.​—Ìfi. 2:10.

A mọ̀ pé táwọn ọ̀tá bá pa wá, Jèhófà máa jí wa dìde. Ó dá wa lójú pé kò sóhun tí wọ́n lè ṣe táá mú ká fi Jèhófà sílẹ̀. (Róòmù 8:35-39) Ẹ ò rí i pé ìrètí àjíǹde yìí jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé Jèhófà jẹ́ ọlọ́gbọ́n! Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù ò bà wá táwọn èèyàn Sátánì bá ń fi ikú halẹ̀ mọ́ wa torí pé a ò ṣe nǹkan tí wọ́n fẹ́ ká ṣe. Bákan náà, ìrètí àjíǹde yìí mú ká nígboyà, ká sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Táwọn ọ̀tá Jèhófà bá fi ikú halẹ̀ mọ́ ẹ, ṣé wàá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà pẹ̀lú ìdánilójú pé á jí ẹ dìde? Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá wàá jẹ́ adúróṣinṣin? Ohun kan tó o lè ṣe ni pé kó o bi ara ẹ pé, ‘Ṣé àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe lójoojúmọ́ fi hàn pé mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?’ (Lúùkù 16:10) Ìbéèrè míì tó o lè bi ara ẹ ni pé, ‘Ṣé bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi fi hàn pé mo gbà pé Jèhófà máa pèsè àwọn ohun tí mo nílò tí mo bá ń fi Ìjọba rẹ̀ sípò àkọ́kọ́?’ (Mát. 6:31-33) Tí ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè yìí bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ó fi hàn pé o ti ṣe tán láti kojú àdánwò èyíkéyìí.​—Òwe 3:5, 6. w20.08 17-18 ¶15-16

Wednesday, July 13

Sa gbogbo ipá rẹ kí o lè rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, kí o jẹ́ òṣìṣẹ́ tí kò ní ohunkóhun tó máa tì í lójú, tó ń lo ọ̀rọ̀ òtítọ́ bó ṣe yẹ.​—2 Tím. 2:15.

A gbọ́dọ̀ já fáfá bá a ṣe ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n ń kọ́ wa bá a ṣe lè já fáfá láwọn ìpàdé wa. Àmọ́ ká tó lè fi dá àwọn míì lójú pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣeyebíye, a gbọ́dọ̀ ní ètò tó ṣe gúnmọ́ láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì máa ṣe é déédéé. Ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára. Èyí kọjá ká kàn máa ka Bíbélì. Ó gba pé ká máa ronú lórí nǹkan tá à ń kà, ká ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa ká lè lóye Ìwé Mímọ́, ká sì mọ bá a ṣe lè fi sílò. (1 Tím. 4:13-15) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn míì lọ́nà tó já fáfá. Ìyẹn kọjá ká kàn ka ẹsẹ Bíbélì fún wọn. Ó gba pé ká jẹ́ kí wọ́n lóye Ìwé Mímọ́ kí wọ́n sì mọ bí wọ́n ṣe máa fi í sílò. Tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, àá túbọ̀ já fáfá nínú bá a ṣe ń fi Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn míì.​—2 Tím. 3:16, 17. w20.09 28 ¶12

Thursday, July 14

Ẹ fara balẹ̀ ronú nípa [Jésù] . . . , kó má bàa rẹ̀ yín, kí ẹ má sì sọ̀rètí nù.​—Héb. 12:3.

Àá lè gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù tá a bá ń ronú nípa àwọn ohun tí Jèhófà ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí ló ń pèsè fún wa nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa, yálà èyí tí wọ́n tẹ̀ jáde tàbí èyí tó wà lórí ẹ̀rọ títí kan àwọn àtẹ́tísí, fídíò àti ètò Tẹlifíṣọ̀n JW. Ẹ tiẹ̀ wò ó ná: Lórí ìkànnì wa, a lè rí ìsọfúnni kà ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000)! (Mát. 24:45-47) Ohun míì tó máa jẹ́ ká gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ni pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Kò jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ láti wàásù ìhìn rere. (Jòh. 18:37) Kò jẹ́ kí “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn” tí Sátánì fi hàn án wọ òun lójú. Bákan náà, kò gbà káwọn èèyàn fi òun jọba. (Mát. 4:8, 9; Jòh. 6:15) Kò jẹ́ kí àwọn ohun ìní tara wọ òun lójú, kò sì jẹ́ kí àtakò dá ìwàásù ìhìn rere náà dúró. (Lúùkù 9:58; Jòh. 8:59) Àá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ta kò wá tá a bá fi ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní sọ́kàn. w20.09 9-10 ¶6-7

Friday, July 15

Ẹ máa fara wé mi, bí èmi náà ṣe ń fara wé Kristi.​—1 Kọ́r. 11:1.

Inú wa dùn pé a ní àwọn arábìnrin tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ! Wọ́n máa ń kópa nínú ìpàdé, wọ́n sì máa ń lọ sóde ẹ̀rí déédéé. Àwọn kan máa ń lọ́wọ́ nínú àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n sì máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará. Síbẹ̀, wọ́n ní àwọn ìṣòro tó ń bá wọn fínra. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ń tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti dàgbà. Àwọn míì ń kojú inúnibíni nínú ìdílé wọn. Òbí tó ń dá tọ́mọ làwọn kan, èyí sì gba pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè bójú tó àwọn ọmọ wọn. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti máa fún àwọn arábìnrin wa níṣìírí? Ìdí ni pé nínú ayé, wọn ò ka àwọn obìnrin sí rárá. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì rọ̀ wá pé ká mọyì àwọn obìnrin, ká sì máa fún wọn níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún ìjọ tó wà ní Róòmù pé kí wọ́n gba Fébè tọwọ́tẹsẹ̀ kí wọ́n sì “ràn án lọ́wọ́ nínú ohun tó bá nílò.” (Róòmù 16:1, 2) Nínú àṣà ìbílẹ̀ ibi tí Pọ́ọ̀lù ti wá, ṣe ni wọ́n máa ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn obìnrin. Àmọ́ lẹ́yìn tó di Kristẹni, ó dẹni tó ń bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin tó sì ń finú rere hàn sí wọn bíi ti Jésù. w20.09 20 ¶1-2

Saturday, July 16

Ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn . . . , ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.​—Mát. 28:​19, 20.

Ta bá fẹ́ kó máa wu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti máa wàásù, a lè bi wọ́n pé: “Báwo làwọn ìlànà Bíbélì tó ò ń fi sílò ṣe mú kí ìgbésí ayé rẹ sunwọ̀n sí i? Ǹjẹ́ o mọ àwọn míì tí ìlànà yìí máa ṣe láǹfààní? Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?” (Òwe 3:27; Mát. 9:37, 38) Ó yẹ ká máa rántí ìtọ́ni tí Jésù fún wa pé ká kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti máa “pa gbogbo ohun” tí Jésù pa láṣẹ fún wa mọ́. Èyí kan àṣẹ méjì tó tóbi jù lọ náà tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò wa. Ìfẹ́ yìí ló ń mú ká máa wàásù ká sì máa sọni dọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 22:37-39) Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àti fún àwọn aládùúgbò wa ló ń mú ká máa wàásù. Ká sòótọ́, ẹ̀rù lè máa ba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti lọ wàásù. Àmọ́ a lè fi dá wọn lójú pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù yìí bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́.​—Sm. 18:1-3; Òwe 29:25. w20.11 3 ¶6-8

Sunday, July 17

A ò dákẹ́ àdúrà lórí yín.​—Kól. 1:9.

Tó o bá ń múra àtilọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lọ́nà tó máa wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Fi sọ́kàn pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bó ṣe máa tẹ̀ síwájú, kó sì ṣèrìbọmi. Ó ṣe pàtàkì pé kí akẹ́kọ̀ọ́ náà máa ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Lọ́nà wo? Ó yẹ kó máa tẹ́tí sí Jèhófà kó sì máa bá a sọ̀rọ̀. Ó lè máa tẹ́tí sí Jèhófà tó bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́. (Jóṣ. 1:8; Sm. 1:1-3) Á máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ tó bá ń gbàdúrà sí i lójoojúmọ́. Máa gbàdúrà àtọkànwá níbẹ̀rẹ̀ àti níparí ìkẹ́kọ̀ọ́ yín, kó o sì dárúkọ ẹ̀ nínú àdúrà náà. Bó ṣe ń fetí sí àdúrà rẹ, á kọ́ bó ṣe lè máa gbàdúrà sí Jèhófà látọkàn wá ní orúkọ Jésù Kristi. (Mát. 6:9; Jòh. 15:16) Ó dájú pé tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ (tó ń tẹ́tí sí Jèhófà), tó sì ń gbàdúrà sí Jèhófà (tó ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀), á túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà!​—Jém. 4:8. w20.10 8 ¶8; 9 ¶10-11

Monday, July 18

Ẹ máa . . . pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.​—Éfé. 4:3.

Lónìí, ètò Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí àlàáfíà lè wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà, kí ohun gbogbo sì máa lọ létòlétò bíi ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. (Ìṣe 16:4, 5) Ẹ jẹ́ ká ṣàkàwé ẹ̀ báyìí: Ká sọ pé o rìnrìn àjò, o sì lọ sípàdé níbẹ̀, ó dájú pé o mọ bí wọ́n ṣe máa darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, o sì mọ àpilẹ̀kọ tí wọ́n máa jíròrò lọ́jọ́ náà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lara ẹ máa silé, o ò sì ní dà bí àjèjì láàárín wọn. Kò sí nǹkan míì tó lè mú kírú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ wà bí kò ṣe ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. (Sef. 3:9) Kí lo lè ṣe? Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mò ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀ nínú ìjọ? Ṣé mo máa ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn tó ń múpò iwájú? Ṣé àwọn míì lè fọkàn tán mi, pàápàá tí mo bá ní àwọn ojúṣe kan nínú ìjọ? Ṣé mi ò kì í pẹ́ lẹ́yìn, ṣé ó sì máa ń yá mi lára láti ṣiṣẹ́ sin àwọn míì?’ (Jém. 3:17) Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Bó o ṣe ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí èrò àti ìwà ẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará á túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ, wọ́n á sì mọyì rẹ nínú ìjọ. w20.10 23 ¶12-13

Tuesday, July 19

Ẹ máa ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ, ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán.​—Jém. 1:22.

Bíbélì fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé dígí. (Jém. 1:23-25) Ọ̀pọ̀ wa la máa ń wo dígí láàárọ̀ ká tó kúrò nílé. Ìyẹn máa ń jẹ́ ká lè ṣe àtúnṣe tó yẹ kó tó di pé a jáde káwọn míì sì rí wa. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, a máa rí àwọn ibi tó ti yẹ ká tún èrò wa tàbí ìwà wa ṣe. Ọ̀pọ̀ máa ń ka ẹsẹ ojúmọ́ láàárọ̀ kí wọ́n tó kúrò nílé torí wọ́n gbà pé ó máa ṣe àwọn láǹfààní. Wọ́n máa ń ronú lé ẹsẹ ojúmọ́ yẹn jálẹ̀ ọjọ́ náà, wọ́n máa ń jẹ́ kó tọ́ àwọn sọ́nà, wọ́n sì máa ń wá àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fi ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sílò. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká máa wáyè láti máa kẹ́kọ̀ọ́ ká sì máa ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́. Lójú wa, ìyẹn lè dà bí ohun tó kéré. Àmọ́ ó wà lára àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá ò bá fẹ́ kúrò lójú ọ̀nà tó há tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ṣe ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí ẹ̀rọ tí wọ́n fi máa ń ṣàyẹ̀wò inú ara lọ́hùn-ún torí ó máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ nínú gan-an. Àmọ́, ká tó lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn Bíbélì àti ìmọ̀ràn táwọn aṣojú Ọlọ́run fún wa, a gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. w20.11 18 ¶3; 20 ¶8

Wednesday, July 20

Àwọn ìjọ túbọ̀ ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́.​—Ìṣe 16:5.

Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, síbẹ̀ àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n wà ní àlàáfíà. Kí ni wọ́n ṣe lásìkò àlàáfíà náà? Gbogbo àwọn Kristẹni yẹn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń fìtara wàásù láìjẹ́ kó sú wọn. Ìwé Ìṣe sọ pé wọ́n “ń rìn nínú ìbẹ̀rù Jèhófà.” Wọ́n ń wàásù ìhìn rere náà, ìyẹn sì mú kí wọ́n máa “gbèrú sí i.” Kò sí àní-àní pé Jèhófà bù kún àwọn èèyàn náà torí ìtara tí wọ́n fi wàásù lásìkò tí àlàáfíà wà yẹn. (Ìṣe 9:26-31) Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lo gbogbo àǹfààní tó yọ láti wàásù ìhìn rere. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti wàásù ní Éfésù, ó wàásù fáwọn èèyàn ìlú náà, ó sì sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (1 Kọ́r. 16:8, 9) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà túbọ̀ tẹra mọ́ wíwàásù “ìhìn rere ọ̀rọ̀ Jèhófà.” (Ìṣe 15:30-35) Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ìdáhùn ẹ̀ wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. w20.09 16 ¶6-8

Thursday, July 21

Ikú . . . wá nípasẹ̀ ẹnì kan.​—1 Kọ́r. 15:21.

Nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ó fa àjálù àti ikú bá òun fúnra ẹ̀ àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Títí dòní la ṣì ń jìyà àìgbọràn tí Ádámù ṣe. Ẹ wo ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ tó wà láàárín ohun tí Ádámù ṣe àtohun tí Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe nígbà tó jí Ọmọ rẹ̀ dìde! Kí ni Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àjíǹde òkú náà wá nípasẹ̀ ẹnì kan,” ìyẹn Jésù. Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Nítorí bí gbogbo èèyàn ṣe ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ gbogbo èèyàn di ààyè nínú Kristi.” (1 Kọ́r. 15:22) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ‘gbogbo èèyàn ń kú nínú Ádámù’? Àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn, torí pé wọ́n ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé látọ̀dọ̀ Ádámù àti pé bópẹ́bóyá àwọn náà máa kú. (Róòmù 5:12) Ádámù ò sí lára àwọn tó máa “di ààyè.” Ìdí ni pé Ádámù ò sí lára àwọn tó máa jàǹfààní ìràpadà Jésù torí ẹni pípé ni àti pé ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ádámù náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tí “Ọmọ èèyàn” bá kà sí “ewúrẹ́,” ìyẹn àwọn tó máa lọ sínú “ìparun àìnípẹ̀kun.”​—Mát. 25:31-33, 46; Héb. 5:9. w20.12 5 ¶13-14

Friday, July 22

Jèhófà . . . ń kíyè sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.​—Sm. 138:6.

Tá ò bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan, ẹ jẹ́ ká ronú nípa àpẹẹrẹ àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́. Nígbà ìṣàkóso Ọba Áhábù, Jèhófà pe àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ pé kí wọ́n sọ àwọn ọ̀nà tí wọ́n rò pé àwọn á lè gbà tan ọba burúkú náà. Onírúurú àbá làwọn áńgẹ́lì yẹn mú wá. Àmọ́ Jèhófà wá yan ọ̀kan lára wọn, ó sì sọ fún un pé àbá tiẹ̀ máa yọrí sí rere. (1 Ọba 22:19-22) Ṣé àwọn áńgẹ́lì yòókù wá rẹ̀wẹ̀sì, bóyá kí wọ́n máa ronú pé, ‘Ká ní mo mọ̀ ni, mi ò bá ti dákẹ́?’ Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé wọ́n ronú bẹ́ẹ̀. Onírẹ̀lẹ̀ làwọn áńgẹ́lì, bí wọ́n sì ṣe máa gbógo fún Jèhófà ló jẹ wọ́n lógún. (Oníd. 13:16-18; Ìfi. 19:10) Mọyì àǹfààní tá a ní pé à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, a sì ń kéde Ìjọba rẹ̀. Kì í ṣe àwọn àǹfààní tá a ní nínú ètò Ọlọ́run ló mú ká ṣeyebíye lójú Jèhófà. Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tá a sì mọ̀wọ̀n ara wa, Jèhófà máa nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, àwọn ará náà sì máa nífẹ̀ẹ́ wa. Torí náà, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kó o sì mọ̀wọ̀n ara ẹ. Máa ronú lórí àpẹẹrẹ àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn nínú Bíbélì. Múra tán láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ará ní gbogbo ọ̀nà tó bá ṣeé ṣe.​—1 Pét. 5:5. w20.12 26 ¶16-17

Saturday, July 23

Ẹ gba akoto ìgbàlà àti idà ẹ̀mí, ìyẹn, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.​—Éfé. 6:17.

Akoto ìgbàlà ni ìrètí tí Jèhófà fún wa, ìyẹn ìrètí pé Jèhófà máa san gbogbo àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́san. Tá a bá sì kú, á jí wa dìde. (1 Tẹs. 5:8; 1 Tím. 4:10; Títù 1:1, 2) Ìrètí tá a ní máa ń dáàbò bò wá ká má bàa ní èrò tí kò tọ́. Ó máa ń jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún wa, kì í sì í jẹ́ ká gbé àwọn ìṣòro wa sọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. À ń lo akoto ìgbàlà yìí tá a bá ń wo nǹkan bí Jèhófà ṣe ń wò ó. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé dípò ọrọ̀. (Sm. 26:2; 104:34; 1 Tím. 6:17) Idà ẹ̀mí ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Idà yìí lè tú àṣírí irọ́ táwọn èèyàn ń pa, kó sì dá wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà burúkú. (2 Kọ́r. 10:4, 5; 2 Tím. 3:16, 17; Héb. 4:12) Tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń fi àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ètò Ọlọ́run fún wa sílò, àá túbọ̀ mọ bó ṣe yẹ ká máa lo idà yìí.​—2 Tím. 2:15. w21.03 27 ¶4; 29 ¶10-11

Sunday, July 24

Mo wà ní erékùṣù tí wọ́n ń pè ní Pátímọ́sì torí mò ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, mo sì ń jẹ́rìí nípa Jésù.​—Ìfi. 1:9.

Ní gbogbo ìgbà tí Jòhánù fi wà ní ẹ̀wọ̀n ní erékùṣù Pátímọ́sì, bó ṣe máa fáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ lókun ló gbà á lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ ìwé Ìfihàn, ó sì fi ránṣẹ́ sáwọn ìjọ kí wọ́n lè mọ “àwọn nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.” (Ìfi. 1:1) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ ní Pátímọ́sì ló kọ ìwé Ìhìn Rere nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó tún kọ lẹ́tà mẹ́ta kó lè fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lókun, kó sì gbé wọn ró. Ìwọ náà lè fi hàn pé o ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ bíi ti Jòhánù, kó o sì fi hàn pé lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ohun tí ayé Sátánì ń fẹ́ ni pé kó o máa lo gbogbo àkókò àti okun ẹ láti wá owó àti òkìkí. Dípò bẹ́ẹ̀, fara wé àwọn Kristẹni tó lẹ́mìí ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n sì ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀. Kárí ayé làwọn Kristẹni yìí ti máa ń lo àkókò àti okun wọn bó ti lè ṣeé ṣe tó láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà. w21.01 10 ¶9-10

Monday, July 25

Jónátánì . . . bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ara rẹ̀.​—1 Sám. 18:1.

Ká sọ pé Jónátánì fẹ́ jowú Dáfídì, ó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ rántí pé Jónátánì ni ọmọ Ọba Sọ́ọ̀lù, òun ló sì yẹ kó rọ́pò bàbá ẹ̀ lẹ́yìn tó bá kú. Bó ti wù kó rí, kò jowú Dáfídì. (1 Sám. 20:31) Ìdí sì ni pé onírẹ̀lẹ̀ ni Jónátánì, ó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Torí náà, tinútinú ló fi fara mọ́ ìpinnu tí Jèhófà ṣe pé kí Dáfídì di ọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Bákan náà, ó tún dúró ti Dáfídì gbágbáágbá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá ẹ̀ ń bínú sí i torí pé ó ń gbè sẹ́yìn Dáfídì. (1 Sám. 20:32-34) Torí pé Jónátánì ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Dáfídì, kò jowú rẹ̀ rárá. Akin lójú ogun ni Jónátánì, atamátàsé sì ni pẹ̀lú. Kódà, àwọn èèyàn máa ń sọ nípa Jónátánì àti Sọ́ọ̀lù bàbá ẹ̀ pé wọ́n “yára ju ẹyẹ idì lọ,” wọ́n sì “lágbára ju kìnnìún lọ.” (2 Sám. 1:22, 23) Torí náà, Jónátánì lè máa fọ́nnu nípa àwọn ohun ribiribi tó ti gbé ṣe lójú ogun, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kò wá bó ṣe máa gbayì ju Dáfídì lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jowú àwọn nǹkan ribiribi tí Dáfídì ṣe lójú ogun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọyì bí Dáfídì ṣe lo ìgboyà tó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì ni Jónátánì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Dáfídì bí ara ẹ̀. w21.01 21 ¶6; 22 ¶8-9

Tuesday, July 26

Orí obìnrin ni ọkùnrin.​—1 Kọ́r. 11:3.

Abẹ́ Jésù Kristi tó jẹ́ ẹni pípé ni gbogbo àwa Kristẹni wà. Àmọ́, tí arábìnrin kan bá ṣègbéyàwó, abẹ́ ọkọ tó jẹ́ aláìpé ló máa wà, ìyẹn kì í sì í rọrùn. Torí náà, tó bá ń ronú nípa ẹni tó máa fẹ́, ó yẹ kó bi ara ẹ̀ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Kí ló fi hàn pé arákùnrin yìí máa jẹ́ olórí ìdílé gidi? Ṣé ìjọsìn Jèhófà ló gbawájú nígbèésí ayé ẹ̀? Tí kò bá fọwọ́ gidi mú ìjọsìn Jèhófà, báwo ni mo ṣe mọ̀ pé ó máa jẹ́ olórí ìdílé gidi lẹ́yìn tá a bá fẹ́ra?’ Síbẹ̀, ó yẹ kí arábìnrin náà bi ara ẹ̀ pé: ‘Ṣé èmi náà ní àwọn ànímọ́ táá jẹ́ kí ìgbéyàwó wa yọrí sí rere? Ṣé mo máa ń mú sùúrù, ṣé mo sì lawọ́? Ṣé mo ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?’ (Oníw. 4:9, 12) Àwọn ìpinnu tí obìnrin kan bá ṣe kó tó ṣègbéyàwó ló máa jẹ́ kó mọ̀ bóyá ìgbéyàwó ẹ̀ á ládùn á sì lóyin. Àpẹẹrẹ àtàtà ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arábìnrin wa tí wọ́n ti ṣègbéyàwó jẹ́ ní ti pé wọ́n ń fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn. Tẹ̀gàn ni hẹ̀, ó yẹ ká gbóríyìn fún wọn! w21.02 8 ¶1-2

Wednesday, July 27

Sọdá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.​—Ìṣe 16:9.

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ń kọ́ èdè míì kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn, kí wọ́n sì lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ló pinnu pé àwọn fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó gbọ́ èdè náà dáadáa, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan ribiribi ni wọ́n ń gbé ṣe. Àwọn ànímọ́ dáadáa tí wọ́n ní àti ìrírí wọn ń gbé ìjọ ró, ó sì ń fáwọn ará lókun. A mà mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa yìí gan-an o! Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kò ní pinnu pé arákùnrin kan kò kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kìkì nítorí pé kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè tí ìjọ náà ń sọ dáadáa. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn arákùnrin gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n ẹ̀ ká tó lè yàn wọ́n làwọn alàgbà fi máa gbé onítọ̀hún yẹ̀ wò, kì í ṣe bó ṣe gbọ́ èdè tí ìjọ náà ń sọ tó.​—1 Tím. 3:1-10, 12, 13; Títù 1:5-9. w20.08 30 ¶15-16

Thursday, July 28

Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀.​—Jém. 1:2.

Àwọn kan ronú pé ó dìgbà tí ìlera àwọn bá jí pépé, táwọn lówó rẹpẹtẹ, tí ilé àwọn sì dùn káwọn tó lè láyọ̀. Àmọ́, ẹ̀mí mímọ́ ló ń mú kéèyàn ní irú ayọ̀ tí Jémíìsì ń sọ yìí, èèyàn sì lè láyọ̀ yìí láìka ìṣòro tó ní sí. (Gál. 5:22) Ohun tó mú káwọn Kristẹni máa láyọ̀ ni pé wọ́n ń múnú Jèhófà dùn, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (Lúùkù 6:22, 23; Kól. 1:10, 11) A lè fi ayọ̀ wé iná tó ń jó nínú láńtánì kan. Ẹyin láńtánì náà ni ò ní jẹ́ kí atẹ́gùn tàbí òjò pa iná tó wà nínú ẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwa náà lè máa láyọ̀ bá a tiẹ̀ ń kojú ìṣòro nígbèésí ayé wa. Ayọ̀ wa ò ní pẹ̀dín tá a bá ń ṣàìsàn tàbí tá ò lówó lọ́wọ́. Kódà, kò ní dín kù táwọn èèyàn bá ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí tí ìdílé wa tàbí àwọn míì ń ta kò wá. Dípò káyọ̀ wa máa dín kù, ṣe lá máa pọ̀ sí i. Àwọn àtakò tá à ń kojú torí ohun tá a gbà gbọ́ jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ọmọ ẹ̀yìn Kristi ni wá. (Mát. 10:22; 24:9; Jòh. 15:20) Ìdí nìyẹn tí Jémíìsì fi sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ wa tòní. w21.02 28 ¶6

Friday, July 29

Ọ̀rọ̀ rere máa ń mú [kí èèyàn] túra ká.​—Òwe 12:25.

Tó o bá rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká fọkàn balẹ̀, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, gbìyànjú láti há wọn sórí. Á dáa kó o kà wọ́n sókè tàbí kó o kọ wọ́n sílẹ̀, kó o lè máa ṣàyẹ̀wò ẹ̀ látìgbàdégbà. Ó ṣe tán, Jèhófà pàṣẹ fún Jóṣúà pé kó máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka Ìwé Òfin déédéé, kó lè máa hùwà ọgbọ́n. Àwọn ìránnilétí tó wà nínú Òfin yẹn máa jẹ́ kó nígboyà, kó sì máa darí àwọn èèyàn Ọlọ́run láìbẹ̀rù. (Jóṣ. 1:8, 9) Ọ̀pọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì ló wà tó máa jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ kódà tó o bá kojú àwọn ìṣòro tó sábà máa ń kó àwọn èèyàn lọ́kàn sókè tàbí dẹ́rù bà wọ́n. (Sm. 27:1-3; Òwe 3:25, 26) A máa ń jàǹfààní látinú àwọn àsọyé tá à ń gbọ́ nípàdé àti látinú ìdáhùn àwọn ará. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń fún ara wa níṣìírí kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ tàbí lẹ́yìn ìpàdé. (Héb. 10:24, 25) Bákan náà, ara máa ń tù wá tá a bá sọ àwọn ìṣòro wa fún ọ̀rẹ́ wa kan tá a fọkàn tán nínú ìjọ. w21.01 6 ¶15-16

Saturday, July 30

Jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn olóòótọ́.​—1 Tím. 4:12.

Nígbà tó o ṣèrìbọmi, o fi hàn pé o nígbàgbọ́, o sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ohun tó o ṣe yẹn múnú Jèhófà dùn, ó sì jẹ́ kó o di ara ìdílé òun. Ohun tó o máa ṣe báyìí ni pé kó o túbọ̀ máa gbára lé Jèhófà. Ó lè rọrùn fún ẹ láti gbára lé Jèhófà tó o bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì. Àmọ́ tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan míì tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ńkọ́? Ó ṣe pàtàkì gan-an kó o máa gbára lé Jèhófà tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu, títí kan eré ìnàjú tó o máa ṣe, iṣẹ́ tó o máa gbà, àtohun tó o máa fayé ẹ ṣe! Má ṣe gbára lé ọgbọ́n ara rẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣèwádìí nínú Bíbélì kó o lè mọ àwọn ìlànà tó bá ipò rẹ mu, kó o sì fi wọ́n sílò. (Òwe 3:5, 6) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá múnú Jèhófà dùn, àwọn tó wà nínú ìjọ á sì fọkàn tán ẹ. Bíi tàwa yòókù, aláìpé nìwọ náà, ìyẹn sì fi hàn pé o lè ṣàṣìṣe. Àmọ́, ìyẹn ò ní kó o má ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. w21.03 6 ¶14-15

Sunday, July 31

Ó . . . gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún.​—2 Tím. 4:17.

Ṣé àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ ń ta kò ẹ́ torí pé ò ń sin Jèhófà? Ṣé orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lò ń gbé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á dáa kó o ka 2 Tímótì 1:12-16 àti 4:6-11, 17-22. Inú ẹ̀wọ̀n ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà nígbà tó kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. Kó o tó ka àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, sọ ìṣòro ẹ fún Jèhófà, kó o sì jẹ́ kó mọ bó ṣe rí lára ẹ. Sọ ohun tó o fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún ẹ gan-an. Lẹ́yìn náà, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o rí àwọn ìlànà tó wà nínú ìtàn Pọ́ọ̀lù táá jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè yanjú ìṣòro náà. Jèhófà ti sọ fún Pọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sí i. (Ìṣe 21:11-13) Báwo ni Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́? Jèhófà dáhùn àdúrà Pọ́ọ̀lù, nígbà tó sì yá, ó fún un lágbára. Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà máa san òun lẹ́san fún iṣẹ́ takuntakun tóun ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Bákan náà, Jèhófà mú kí àwọn ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù ràn án lọ́wọ́. w21.03 17-18 ¶14-15, 19

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́