August
Monday, August 1
Láìsí èmi, ẹ ò lè ṣe ohunkóhun.—Jòh. 15:5.
Àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù nìkan ló máa jàǹfààní ẹbọ ìràpadà rẹ̀. Jésù sọ pé òun máa fi ‘ẹ̀mí òun lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ òun.’ (Jòh. 15:13) Àwọn olóòótọ́ tó gbáyé kí Jésù tó wá sáyé ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Jèhófà máa jí àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ dìde, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ di ọ̀rẹ́ Jésù kí wọ́n tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 17:3; Ìṣe 24:15; Héb. 11:8-12, 24-26, 31) Inú wa ń dùn bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jésù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tá a sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Olùkọ́ ni Jésù nígbà tó wà láyé. Lẹ́yìn tó pa dà sọ́run, ó di orí ìjọ, àtìgbà yẹn ló sì ti ń darí iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni tá à ń ṣe. Ó ń rí gbogbo bó o ṣe ń sapá láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ òun àti Jèhófà, ó sì mọyì ìsapá rẹ gan-an. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò sí bá a ṣe lè ṣe iṣẹ́ yìí yanjú láìjẹ́ pé Jèhófà àti Jésù ràn wá lọ́wọ́.—Jòh. 15:4. w20.04 22 ¶7-8
Tuesday, August 2
Ọba méjì yìí . . . máa jókòó sídìí tábìlì kan náà, wọ́n á máa parọ́ fúnra wọn.—Dán. 11:27.
Níbẹ̀rẹ̀, gbólóhùn náà “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” tọ́ka sí àwọn ọba tó ṣàkóso láwọn ilẹ̀ tó wà lápá àríwá àti gúúsù orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (Dán. 10:14) Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni àwọn èèyàn Ọlọ́run títí dìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ látìgbà yẹn wá, Jèhófà mú kó ṣe kedere pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó jẹ́ olóòótọ́ ni àwọn èèyàn òun. Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ni èyí tó pọ̀ jù lára àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì orí kọkànlá (11) kàn, kì í ṣe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (Ìṣe 2:1-4; Róòmù 9:6-8; Gál. 6:15, 16) Àmọ́ látìgbàdégbà ni ìyípadà ń bá àwọn tó jẹ́ ọba àríwá àti ọba gúúsù. Bó ti wù kó rí, àwọn nǹkan kan wà tí kò yí pa dà. Àkọ́kọ́, àwọn ọba yẹn ń ṣàkóso lé àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí tàbí kí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn. Ìkejì, bí wọ́n ṣe ń fojú pọ́n àwọn èèyàn Ọlọ́run fi hàn pé wọ́n kórìíra Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́. Kókó kẹta ni pé àwọn ọba méjèèjì yìí máa ń bá ara wọn jà láti mọ ẹni tó jẹ́ ọ̀gá. w20.05 3 ¶3-4
Wednesday, August 3
Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Fẹ́.—Ẹ́kís. 3:14.
Jèhófà máa ń mú kí nǹkan di ní ti pé ó máa ń di ohunkóhun tó bá yẹ láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ máa ń di ohunkóhun láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, ó tún máa ń lo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ tá a jẹ́ aláìpé láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. (Àìsá. 64:8) Yálà fúnra rẹ̀ tàbí nípasẹ̀ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, Jèhófà máa ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Ó dájú pé kò sí nǹkan kan láyé yìí tó lè dí i lọ́wọ́. (Àìsá. 46:10, 11) Ká lè túbọ̀ mọyì Baba wa ọ̀run, ó yẹ ká máa ronú nípa àwọn nǹkan tó ti ṣe àtàwọn ohun tó mú káwa náà ṣe. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń túbọ̀ mọyì àwọn nǹkan ribiribi tí Jèhófà ṣe bá a ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan tó dá. (Sm. 8:3, 4) Tá a bá sì ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti mú ká ṣe láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, ọ̀wọ̀ tá a ní fún un á túbọ̀ jinlẹ̀. Ká sòótọ́, orúkọ tó yẹ kéèyàn bọ̀wọ̀ fún lorúkọ Jèhófà! Ìdí sì ni pé orúkọ yẹn jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, àwọn ohun tó ti ṣe àtàwọn nǹkan tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.—Sm. 89:7, 8. w20.06 9-10 ¶6-7
Thursday, August 4
Ọlọ́run . . . ń fún gbogbo èèyàn ní ìyè àti èémí.—Ìṣe 17:24, 25.
Afẹ́fẹ́ oxygen tí àwa èèyàn àtàwọn ẹranko ń mí sínú ló ń jẹ́ ká wà láàyè. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fojú bù ú pé ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù tọ́ọ̀nù afẹ́fẹ́ oxygen ni àwa èèyàn àtàwọn ẹranko ń mí sínú lọ́dún. Àwọn ohun alààyè yìí kan náà ń mí afẹ́fẹ́ carbon dioxide síta, èyí tá a lè fi wé ìdọ̀tí. Síbẹ̀, àwa èèyàn àtàwọn ẹranko ò lo afẹ́fẹ́ oxygen tó wà nínú ayé yìí tán, bẹ́ẹ̀ sì ni afẹ́fẹ́ carbon dioxide tá à ń mí síta kò gba ilé ayé kan. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe? Ìdí ni pé Jèhófà dá àwọn ewéko, igi àtàwọn nǹkan tín-tìn-tín tí wọ́n ń lo afẹ́fẹ́ carbon dioxide tí wọ́n sì ń tú afẹ́fẹ́ oxygen síta. Ìyípo afẹ́fẹ́ oxygen yìí mú kí ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní túbọ̀ ṣe kedere. Kò sí àní-àní pé ẹ̀bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni ayé wa yìí àtàwọn nǹkan rere míì tí Jèhófà dá sínú ẹ̀. Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ mọyì wọn? (Sm. 115:16) Ọ̀kan lára ohun tá a lè ṣe ni pé ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Èyí á mú ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lójoojúmọ́ fáwọn nǹkan rere tó ń pèsè fún wa. Ohun míì tá a lè ṣe ni pé ká jẹ́ kí àyíká wa máa wà ní mímọ́ tónítóní nígbà gbogbo. w20.05 22 ¶5, 7
Friday, August 5
Ó dájú pé màá sọ orúkọ ńlá mi di mímọ́, èyí tí wọ́n kó ẹ̀gàn bá láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.—Ìsík. 36:23.
Bí Jèhófà ṣe yanjú ọ̀rọ̀ Sátánì fi hàn pé ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, onísùúrù àti onídàájọ́ òdodo. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì fi hàn pé kò sẹ́ni tó lágbára bíi tòun. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ìfẹ́ rẹ̀ hàn nínú gbogbo ohun tó ń ṣe. (1 Jòh. 4:8) Ó ṣe kedere pé àtìgbà yẹn ni Jèhófà ti ń sọ orúkọ ara rẹ̀ di mímọ́. Títí dòní, Sátánì ṣì ń ba Jèhófà lórúkọ jẹ́. Ó ń mú káwọn èèyàn máa ronú pé bóyá ni Ọlọ́run jẹ́ alágbára, onídàájọ́ òdodo, ọlọ́gbọ́n àti onífẹ̀ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Sátánì ń mú káwọn èèyàn gbà pé kì í ṣe Jèhófà ló dá ayé yìí àtàwọn nǹkan míì. Tó bá sì ráwọn tó gbà pé Ọlọ́run wà, ó máa ń fẹ́ mú kí wọ́n gbà pé àwọn òfin Ọlọ́run ti le jù àti pé kò lójú àánú. Kódà, ó tún ń kọ́ àwọn èèyàn pé ìkà àti òṣónú ni Jèhófà, pé ó máa jó àwọn èèyàn nínú iná ọ̀run àpáàdì. Tí wọ́n bá sì ti gba irọ́ yìí gbọ́, ṣe ni wọ́n máa kẹ̀yìn sí Jèhófà. Ó dìgbà tí Jèhófà bá pa Sátánì run kó tó dẹ́kun àtimáa gbìyànjú láti mú kíwọ náà kẹ̀yìn sí Jèhófà. Ṣé wàá gbà fún un? w20.06 5 ¶13-15
Saturday, August 6
Kò . . . sí Gíríìkì tàbí Júù, ìdádọ̀dọ́ tàbí àìdádọ̀dọ́, àjèjì, Sítíánì, ẹrú tàbí òmìnira; àmọ́ Kristi ni ohun gbogbo, ó sì wà nínú ohun gbogbo.—Kól. 3:11.
Kò sígbà tá ò ní rí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè nínú ìjọ wa. Ó lè ṣòro fún wọn láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Síbẹ̀ tá a bá wò wọ́n dáadáa, àá rí i pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ tọkàntọkàn bí wọn ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ gbédè wa. Tá a bá fara balẹ̀, àá kíyè sáwọn ànímọ́ dáadáa tí wọ́n ní, ìyẹn á sì mú ká túbọ̀ mọyì wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, a ò ní sọ pé “mi ò nílò rẹ” kìkì nítorí pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbédè wa. (1 Kọ́r. 12:21) Àǹfààní ńlá ni Jèhófà fún wa bó ṣe jẹ́ ká wà nínú ìjọ rẹ̀. Yálà ọkùnrin ni wá tàbí obìnrin, a ti ṣègbéyàwó tàbí a ò tíì ṣe, bóyá ọmọdé ni wá tàbí àgbà, yálà a gbédè tàbí a ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́, gbogbo wa pátá ni Jèhófà mọyì, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló sì wúlò nínú ìjọ. (Róòmù 12:4, 5; Kól. 3:10) Torí náà, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé a wúlò nínú ìjọ, ká sì túbọ̀ mọyì àwọn míì tá a jọ wà nínú ìjọ. w20.08 31 ¶20-22
Sunday, August 7
Àwọn kan dara pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di onígbàgbọ́.—Ìṣe 17:34.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé àwọn èèyàn Áténì lè di ọmọ ẹ̀yìn bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbọ̀rìṣà, ìṣekúṣe àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí ló kún ìlú náà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí wọ́n sọ sí òun mú kóun rẹ̀wẹ̀sì. Ẹ rántí pé kí Pọ́ọ̀lù alára tó di Kristẹni, ó jẹ́ ‘asọ̀rọ̀ òdì, ó máa ń ṣe inúnibíni, ó sì jẹ́ aláfojúdi.’ (1 Tím. 1:13) Bí Jésù ṣe gbà pé Pọ́ọ̀lù lè di ọmọ ẹ̀yìn òun náà ni Pọ́ọ̀lù gbà pé àwọn èèyàn Áténì lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn torí pé àwọn kan lára wọn di ọmọ ẹ̀yìn. (Ìṣe 9:13-15) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, onírúurú èèyàn ló di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó sọ pé àwọn kan lára wọn ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀daràn àti oníṣekúṣe. Ó wá sọ pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín jẹ́ tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ a ti wẹ̀ yín mọ́.” (1 Kọ́r. 6:9-11) Tó bá jẹ́ ìwọ ni, ṣé wàá gbà pé àwọn èèyàn yẹn lè yí pa dà kí wọ́n sì dọmọ ẹ̀yìn? w20.04 12 ¶15-16
Monday, August 8
Ó tó gẹ́ẹ́! . . . Gba ẹ̀mí mi.—1 Ọba 19:4.
Ó ṣeé ṣe káwọn kan nínú ìjọ máa ṣiyèméjì pé bóyá làǹfààní wà nínú báwọn ṣe ń sin Jèhófà. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin alàgbà ò gbọ́dọ̀ dá wọn lẹ́bi tàbí kẹ́ ẹ pa wọ́n tì. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni kẹ́ ẹ sapá láti mọ ìdí tí wọ́n fi ń ṣiyèméjì. Ìgbà yẹn lẹ tó lè mọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táá ràn wọ́n lọ́wọ́ táá sì fún wọn níṣìírí. Wòlíì Èlíjà sá lọ nítorí Ayaba Jésíbẹ́lì. (1 Ọba 19:1-3) Ó ronú pé asán ni gbogbo iṣẹ́ tóun ṣe. Kódà, ẹ̀dùn ọkàn bá a débi tó fi gbàdúrà pé kóun kú. (1 Ọba 19:10) Jèhófà ò dá Èlíjà lẹ́bi, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló fi dá a lójú pé òun nìkan kọ́ ló ń sin Jèhófà nílẹ̀ Ísírẹ́lì, pé àwọn míì ṣì wà. Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ fún un pé òun máa tì í lẹ́yìn àti pé iṣẹ́ ṣì pọ̀ fún un láti ṣe. Jèhófà tẹ́tí sí gbogbo ohun tí Èlíjà sọ, ó sì gbé iṣẹ́ míì fún un. (1 Ọba 19:11-16, 18) Kí la rí kọ́? Gbogbo wa, ní pàtàkì àwọn alàgbà ló yẹ kó máa fìfẹ́ hàn sáwọn àgùntàn Jèhófà. Ohun yòówù kẹ́nì kan sọ tàbí ṣe, kódà tó bá tiẹ̀ sọ pé Jèhófà kò lè dárí ji òun, tàbí kẹ̀ tí inú ń bí i, ó yẹ kẹ́yin alàgbà fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ fi dá a lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, ó sì mọyì rẹ̀. w20.06 22 ¶13-14
Tuesday, August 9
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo.—Òwe 17:17.
Jèhófà fẹ́ ká máa gbádùn ìfararora pẹ̀lú àwọn tá a jọ wà nínú ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ wa míì. (Sm. 133:1) Jésù náà láwọn ọ̀rẹ́ gidi. (Jòh. 15:15) Bíbélì sọ àǹfààní téèyàn máa ń rí tó bá láwọn ọ̀rẹ́ gidi. (Òwe 18:24) Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ ká ya ara wa sọ́tọ̀. (Òwe 18:1) Àwọn kan gbà pé ìkànnì àjọlò máa jẹ́ káwọn ní ọ̀rẹ́ tó pọ̀ káwọn má sì dá wà. Àmọ́ ó yẹ ká ṣọ́ra tá a bá ń lo ìkànnì àjọlò. Ìwádìí fi hàn pé àwọn tó máa ń gbé fọ́tò sórí ìkànnì àjọlò ṣáá tí wọ́n sì máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti yẹ ohun táwọn míì gbé síbẹ̀ wò máa ń dá wà, wọn kì í sì í láyọ̀. Kí nìdí? Ohun kan ni pé fọ́tò wọn tó dáa jù àtàwọn nǹkan tó jọjú táwọn èèyàn ṣe ni wọ́n máa ń gbé sórí ìkànnì yìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń gbé fọ́tò àwọn ibi tí wọ́n lọ, bí wọ́n ṣe gbádùn ara wọn, fọ́tò àwọn ọ̀rẹ́ wọn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sórí ìkànnì náà. Tẹ́nì kan bá jókòó ti àwọn fọ́tò náà, ó lè gbà pé ìgbésí ayé òun ò nítumọ̀ àti pé òun ò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn tó kù. w20.07 5-6 ¶12-13
Wednesday, August 10
Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà kóra jọ láti gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò.—Ìṣe 15:6.
Ilé-Ìṣọ́nà October 1, 1988 sọ pé: “Àwọn alàgbà máa ń fi sọ́kàn pé Kristi lè tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ darí èrò èyíkéyìí lára àwọn alàgbà láti sọ ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ kí wọ́n yanjú ìṣòro èyíkéyìí tàbí táá jẹ́ kí wọ́n ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan. (Ìṣe 15:7-15) Kò sí alàgbà kankan tó lè sọ pé òun nìkan lẹ̀mí mímọ́ ń ṣiṣẹ́ lára rẹ̀.” Alàgbà kan tó ń bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà míì kò ní jẹ́ pé òun lá máa kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìpàdé àwọn alàgbà. Kì í gba ọ̀rọ̀ mọ́ àwọn míì lẹ́nu kó lè sọ tiẹ̀, ó sì máa ń dẹ́nu dúró káwọn míì lè sọ̀rọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, kì í ronú pé òun nìkan lòun gbọ́n tàbí pé ọ̀rọ̀ tòun nìkan làwọn yòókù gbọ́dọ̀ gbà. Dípò bẹ́ẹ̀, ó máa ń fìrẹ̀lẹ̀ sọ èrò ẹ̀, kì í sì í rin kinkin mọ́ ohun tó bá sọ. Bákan náà, ó máa ń fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn míì. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó máa ń ṣe tán láti jíròrò àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́, ó sì máa ń yá a lára láti tẹ̀ lé ìtọ́ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mát. 24:45-47) Táwọn alàgbà bá ń fìfẹ́ hàn, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn nínú ìpàdé àwọn alàgbà, ẹ̀mí mímọ́ máa wà pẹ̀lú wọn, á sì mú kí wọ́n ṣèpinnu tó tọ́.—Jém. 3:17, 18. w20.08 27 ¶5-6
Thursday, August 11
Máa fi ire ṣẹ́gun ibi.—Róòmù 12:21.
Àwọn ọ̀tá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pọ̀, wọ́n sì lágbára jù ú lọ. Àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n nà án, tí wọ́n sì sọ ọ́ sẹ́wọ̀n. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó yẹ kó jẹ́ ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù ló hùwà àìdáa sí i. Kódà, àwọn kan nínú ìjọ tún ta kò ó. (2 Kọ́r. 12:11; Fílí. 3:18) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù borí gbogbo àwọn alátakò rẹ̀. Lọ́nà wo? Ó ń bá iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lọ láìka àtakò sí. Ó ṣì nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ̀ kódà nígbà tí wọ́n já a kulẹ̀. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (2 Tím. 4:8) Ohun tó mú kó jẹ́ adúróṣinṣin délẹ̀ ni pé kò gbẹ́kẹ̀ lé ara ẹ̀, Jèhófà ló gbẹ́kẹ̀ lé. Ṣé gbogbo ìgbà làwọn èèyàn máa ń bẹnu àtẹ́ lù ẹ́? Ohun tá a fẹ́ ni pé kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ wọ́n lọ́kàn kó sì mú kí wọ́n ṣe ohun tó tọ́. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè àwọn èèyàn, tá à ń bọ̀wọ̀ fáwọn tó hùwà àìdáa sí wa, tá a sì ń ṣe ohun tó dáa sí gbogbo èèyàn títí kan àwọn tó kórìíra wa.—Mát. 5:44; 1 Pét. 3:15-17. w20.07 17-18 ¶14-15
Friday, August 12
Ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì sọ mí di ẹni ńlá.—2 Sám. 22:36.
Ṣé lóòótọ́ ni Jèhófà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, bí Dáfídì ṣe sọ nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní. (Sm. 18:35) Nígbà tí Dáfídì kọrin yìí, ó ṣeé ṣe kó máa rántí ọjọ́ tí wòlíì Sámúẹ́lì wá sílé wọn, tó sì fi òróró yàn án pé òun ló máa di ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Dáfídì ló kéré jù nínú àwọn ọmọkùnrin mẹ́jọ tí bàbá wọn bí, síbẹ̀ òun ni Jèhófà yàn láti rọ́pò Ọba Sọ́ọ̀lù. (1 Sám. 16:1, 10-13) Kò sí àní-àní pé Dáfídì máa gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí onísáàmù kan sọ nípa Jèhófà pé: “Ó tẹ̀ ba láti wo ọ̀run àti ayé, ó ń gbé aláìní dìde látinú eruku. Ó ń gbé tálákà dìde . . . kí ó lè mú un jókòó pẹ̀lú àwọn èèyàn pàtàkì.” (Sm. 113:6-8) Jèhófà fi hàn pé òun lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nínú bó ṣe ń bá àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ aláìpé lò. Kì í ṣe pé ó tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa nìkan, ó tún mú wa lọ́rẹ̀ẹ́. (Sm. 25:14) Kíyẹn lè ṣeé ṣe, Jèhófà pèsè Ọmọ rẹ̀ pé kó wá kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run ń ṣàánú wa gan-an, ó sì ń gba tiwa rò! w20.08 8 ¶1-3
Saturday, August 13
[Jèhófà] kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.—2 Pét. 3:9.
Jèhófà ti yan ọjọ́ àti wákàtí tó máa pa ayé búburú yìí run. (Mát. 24:36) Àmọ́ kò ní fi ìkánjú ṣe bẹ́ẹ̀ ṣáájú àkókò yẹn. Ó wù ú gan-an pé kó jí àwọn tó ti kú dìde, síbẹ̀ ó ń mú sùúrù. (Jóòbù 14:14, 15) Ó ń dúró de àsìkò tó tọ́ láti jí wọn dìde. (Jòh. 5:28) Torí náà, ó yẹ ká mọyì sùúrù Jèhófà. Rò ó wò ná: Tí kì í bá ṣe pé Jèhófà mú sùúrù, ṣé á ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan ìwọ náà láti “ronú pìwà dà”? Jèhófà fẹ́ kí gbogbo èèyàn ní ìyè àìnípẹ̀kun tó bá ṣeé ṣe. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì sùúrù Jèhófà. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fi taratara wá “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun.” Ẹ jẹ́ ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì wá sìn ín. (Ìṣe 13:48) Èyí á mú káwọn náà jàǹfààní sùúrù Jèhófà bíi tiwa. w20.08 18 ¶17
Sunday, August 14
Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.—Sm. 25:4.
Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ wọ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́kàn, kì í ṣe kó kàn kó ìmọ̀ ságbárí. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó dìgbà tó bá wọ̀ ọ́ lọ́kàn kó tó lè gbé ìgbésẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀kọ́ Jésù máa ń bọ́gbọ́n mu, àwọn èèyàn sì fẹ́ràn láti máa tẹ́tí sí i. Àmọ́ ohun tó mú kí wọ́n tẹ̀ lé e ni pé ẹ̀kọ́ náà máa ń wọ̀ wọ́n lọ́kàn. (Lúùkù 24:15, 27, 32) Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni gidi sí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ, kó ṣe tán láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀, kó sì mú Jèhófà ní Baba, Ọlọ́run àti Ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Sm. 25:5) Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ yín, máa tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní. (Ẹ́kís. 34:5, 6; 1 Pét. 5:6, 7) Láìka àkòrí tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò sí, pe àfíyèsí ẹ̀ sí irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ràn án lọ́wọ́ kó lè mọyì bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, onínúure, tó sì ń gba tẹni rò. Jésù sọ pé “àṣẹ tó tóbi jù lọ, tó sì jẹ́ àkọ́kọ́” ni pé ká “nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run” wa. (Mát. 22:37, 38) Torí náà, ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkàn wá. w20.10 10 ¶12
Monday, August 15
Jésù fẹ́ràn Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù.—Jòh. 11:5.
Gbogbo obìnrin ni Jésù máa ń buyì fún. (Jòh. 4:27) Àmọ́, Jésù mọyì àwọn obìnrin tó ń ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀ gan-an. Kódà, ó pè wọ́n ní arábìnrin òun, ó gbà pé àwọn obìnrin yìí àtàwọn ọkùnrin tó ń tẹ̀ lé òun jọ wà nínú ìdílé kan náà pẹ̀lú òun. (Mát. 12:50) Jésù tún mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo ọwọ́ tó fi mú Màtá àti Màríà tó ṣeé ṣe kí wọ́n wà láìlọ́kọ. (Lúùkù 10:38-42) Jésù máa ń mú kára tù wọ́n kọ́kàn wọn sì balẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe ẹ̀. Kódà, ọkàn Màríà balẹ̀ láti jókòó síbi ẹsẹ̀ Jésù. Yàtọ̀ síyẹn, ó yá Màtá lára láti fẹjọ́ sun Jésù pé Màríà ò ran òun lọ́wọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ó rọrùn fún Jésù láti kọ́ àwọn méjèèjì lẹ́kọ̀ọ́. Jésù sì fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn obìnrin yìí àti Lásárù arákùnrin wọn torí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló ń dé sọ́dọ̀ wọn. (Jòh. 12:1-3) Abájọ tó fi yá Màtá àti Màríà lára láti ránṣẹ́ pe Jésù nígbà tí Lásárù ń ṣàìsàn.—Jòh. 11:3. w20.09 20 ¶3; 21 ¶6
Tuesday, August 16
Wọ́n . . . rò pé Ìjọba Ọlọ́run máa fara hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.—Lúùkù 19:11.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù retí pé kí Ìjọba Ọlọ́run “fara hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀” kó sì dá wọn nídè lọ́wọ́ àwọn ará Róòmù. Ó wu àwa náà pé kí Ìjọba Ọlọ́run tètè mú ìwà burúkú kúrò láyé, kó sì mú ayé tuntun òdodo wá. (2 Pét. 3:13) Àmọ́, a gbọ́dọ̀ mú sùúrù títí dìgbà tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà. Jèhófà fún Nóà “oníwàásù òdodo” ní àkókò tó pọ̀ tó láti fi kan ọkọ̀ áàkì kó sì wàásù. (2 Pét. 2:5; 1 Pét. 3:20) Jèhófà fara balẹ̀ tẹ́tí sí Ábúráhámù nígbà tó ń béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ léraléra pé kí nìdí tó fi máa pa Sódómù àti Gòmórà run. (Jẹ́n. 18:20-33) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà fi mú sùúrù fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí wọ́n ya aláìgbọràn. (Neh. 9:30, 31) Bákan náà, Jèhófà ń mú sùúrù lónìí kí gbogbo àwọn tó fẹ́ kó wá sọ́dọ̀ òun lè “ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9; Jòh. 6:44; 1 Tím. 2:3, 4) Àwọn àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwa náà máa mú sùúrù bá a ṣe ń wàásù tá a sì ń kọ́ni. w20.09 10 ¶8-9
Wednesday, August 17
Àjíǹde . . . yóò wà.—Ìṣe 24:15.
Nígbà tí Jèhófà bá jí àwọn òkú dìde ó máa mú kí wọ́n rántí ohun tí wọ́n ṣe sẹ́yìn, ojú wọn, ohùn wọn àti èrò wọn á sì rí bíi ti tẹ́lẹ̀. Ẹ wo ohun tíyẹn túmọ̀ sí ná. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ débi pé ó ń kíyè sí ẹ, ó mọ ohun tó ò ń rò báyìí, ó mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ, bó o ṣe ń sọ̀rọ̀ àtàwọn nǹkan tó ò ń ṣe. Torí náà, tó bá di pé kó jí ẹ dìde, kò ní ṣòro fún un láti mú kó o rántí ohun tó o ṣe sẹ́yìn, á sì mú kí ojú rẹ, ohùn rẹ àti èrò rẹ rí bíi ti tẹ́lẹ̀. Ọba Dáfídì náà mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọ̀ wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Sm. 139:1-4) Báwo ló ṣe rí lára wa pé Jèhófà mọ̀ wá gan-an? Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe mọ̀ wá tó, kò yẹ káyà wa máa já pé ṣe ló ń ṣọ́ wa lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀. Kí nìdí? Ká rántí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, kò sì fọ̀rọ̀ wa ṣeré. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni Jèhófà kà sí, ó sì mọyì wa. Ó mọ̀ wá dunjú, ó mọ nǹkan tá à ń ṣe, ó sì mọ àwọn nǹkan tó jẹ́ ká yàtọ̀ sáwọn míì. Ẹ ò rí i pé ìyẹn fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Torí náà, ká máa rántí pé a ò dá wà. Gbogbo ìgbà ni ojú Jèhófà wà lára wa, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́.—2 Kíró. 16:9. w20.08 17 ¶13-14
Thursday, August 18
Màá fún ọ ní ìjìnlẹ̀ òye, màá sì kọ́ ọ ní ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.—Sm. 32:8.
Tayọ̀tayọ̀ ni Jèhófà fi dá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Ó fẹ́ kí gbogbo wọn mọ òun, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun, kí wọ́n sì wà láàyè títí láé. Àmọ́, àwọn nǹkan yìí kò ní ṣeé ṣe láìjẹ́ pé Jèhófà dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Jòh. 17:3) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ìjọ Kristẹni ni Jèhófà lò láti dá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. (Kól. 1:9, 10) Ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn “olùrànlọ́wọ́” tí Jésù ṣèlérí ló jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe. (Jòh. 14:16) Ó jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì jẹ́ kí wọ́n rántí ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jésù kọ́ wọn àtàwọn nǹkan tó ṣe, èyí tó wà lákọsílẹ̀ nígbà tó yá nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere. Ohun tí wọ́n mọ̀ yìí mú kí ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni yẹn túbọ̀ lágbára, ó sì mú kí wọ́n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jésù, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní kejì. Lóde òní, Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè máa wá sí òkè mímọ́ òun kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun. (Àìsá. 2:2, 3) À ń rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí lónìí. w20.10 24 ¶14-15
Friday, August 19
Olóye máa ń gba ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n.—Òwe 1:5.
Kí ló lè mú kẹ́nì kan kọ ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún un? Ìgbéraga ló lè mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn agbéraga máa ń fẹ́ káwọn èèyàn “sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́” fún wọn. Torí náà, “wọn [kì í] fetí sí òtítọ́.” (2 Tím. 4:3, 4) Wọ́n máa ń ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ. Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Tí ẹnì kan bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni.” (Gál. 6:3) Ọ̀rọ̀ Ọba Sólómọ́nì bá a mu rẹ́gí, ó ní: “Ọmọdé tó jẹ́ aláìní àmọ́ tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n sàn ju àgbàlagbà ọba tó jẹ́ òmùgọ̀, tí làákàyè rẹ̀ kò tó láti gba ìkìlọ̀ mọ́.” (Oníw. 4:13) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí àpọ́sítélì Pétérù ṣe nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá a wí lójú gbogbo èèyàn. (Gál. 2:11-14) Pétérù lè máa bínú sí Pọ́ọ̀lù nítorí bó ṣe bá a sọ̀rọ̀, àti pé ó bá a wí lójú gbogbo èèyàn. Àmọ́ Pétérù ò ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ọlọ́gbọ́n ni. Ó gba ìbáwí tí Pọ́ọ̀lù fún un, kò sì dì í sínú. Kódà nígbà tó yá, ó pe Pọ́ọ̀lù ní “arákùnrin wa ọ̀wọ́n.”—2 Pét. 3:15. w20.11 21 ¶9, 11-12
Saturday, August 20
Ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn . . . , ẹ máa kọ́ wọn.—Mát. 28:19, 20.
Kí ló máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan túbọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? Ohun kan ni pé kó máa wá sípàdé déédéé. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tó ń gbọ́ nípàdé á mú kó túbọ̀ lóye òtítọ́, kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára, kó sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Ìṣe 15:30-32) Yàtọ̀ síyẹn, arákùnrin kan lè ṣàlàyé fún akẹ́kọ̀ọ́ yẹn pé ìfẹ́ tóun ní fún Jèhófà ló mú kóun jáwọ́ nínú àṣà burúkú kan. (2 Kọ́r. 7:1; Fílí. 4:13) Báwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ará tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn nípa bá a ṣe lè pa àṣẹ Jésù mọ́ tó ní ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn. (Jòh. 13:35; 1 Tím. 4:12) Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ará tó ti dojú kọ irú àwọn ìṣòro tóun náà ní báyìí. Àpẹẹrẹ àwọn ará yẹn máa jẹ́ kóun náà mọ̀ pé òun á lè ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ láti di ọmọlẹ́yìn Kristi. (Diu. 30:11) Ó ṣe kedere nígbà náà pé gbogbo wa pátá la lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—Mát. 5:16. w20.11 5 ¶10-12
Sunday, August 21
Mo ti bá àwọn ẹranko jà ní Éfésù.—1 Kọ́r. 15:32.
Ó lè jẹ́ ìgbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá àwọn ẹranko gidi jà ní gbọ̀ngàn ìwòran tó wà ní Éfésù ló ní lọ́kàn. (2 Kọ́r. 1:8; 4:10; 11:23) Ó sì lè jẹ́ àtakò látọ̀dọ̀ àwọn Júù àtàwọn míì tó ń hùwà bí “ẹranko” ló ní lọ́kàn. (Ìṣe 19:26-34; 1 Kọ́r. 16:9) Èyí ó wù ó jẹ́, ó ṣe kedere pé ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù wà nínú ewu. Síbẹ̀ ó gbà pé tóun bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí òun dìde. (1 Kọ́r. 15:30, 31; 2 Kọ́r. 4:16-18) Àsìkò tá à ń gbé yìí léwu gan-an, àwọn ará wa kan ń gbé láwọn ilẹ̀ tí ìwà ọ̀daràn ti gbilẹ̀, ojú wọn sì máa ń rí màbo. Àwọn míì ń gbé láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti ń jagun, ọ̀pọ̀ ìgbà sì lẹ̀mí wọn máa ń wà nínú ewu. Bákan náà, àwọn ará wa kan ń gbé láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Síbẹ̀, wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà nìṣó bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè jù wọ́n sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n pa wọ́n. Láìka ipò táwọn ará yìí dojú kọ, wọn ò dẹwọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà, àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n sì jẹ́ fún wa. Ọkàn wọn balẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé tí àwọn bá tiẹ̀ kú nísinsìnyí, Jèhófà máa jí àwọn dìde lọ́jọ́ iwájú, á sì san àwọn lẹ́san. w20.12 9 ¶3-4
Monday, August 22
Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá. Ẹ̀yin jẹ́ pápá Ọlọ́run tí à ń ro lọ́wọ́, ilé Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 3:9.
Ǹjẹ́ a rígbà kan tó o rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé ìpínlẹ̀ ìwàásù yín ò méso jáde tàbí nítorí pé ẹ kì í fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn èèyàn nílé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó o láyọ̀? Ó ṣe pàtàkì ká ní èrò tó tọ́ nípa iṣẹ́ ìwàásù wa. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Fi sọ́kàn pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká kéde orúkọ Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ fáwọn èèyàn. Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn díẹ̀ ló máa rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè. (Mát. 7:13, 14) Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ ìwàásù mú ká láǹfààní láti máa bá Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ṣiṣẹ́. (Mát. 28:19, 20; Ìfi. 14:6, 7) Bákan náà, Jèhófà ló máa ń fa àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀. (Jòh. 6:44) Torí náà, tẹ́nì kan ò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ wa nígbà àkọ́kọ́, ó lè tẹ́tí sí wa nígbà míì. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Deborah sọ pé: “Irinṣẹ́ tó lágbára ni ìrẹ̀wẹ̀sì jẹ́ lọ́wọ́ Sátánì.” Àmọ́, Jèhófà lágbára ju Sátánì àtàwọn nǹkan ìjà ogun ẹ̀ lọ. w20.12 26 ¶18-19; 27 ¶21
Tuesday, August 23
Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa, torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá.—1 Jòh. 4:7.
Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni olóòótọ́ ló ń ṣiṣẹ́ bó-o-jí-o-jí-mi kí wọ́n lè pèsè fún ara wọn àti ìdílé wọn. Síbẹ̀ àwọn ará yìí ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ti ètò Ọlọ́run lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ nígbà àjálù, àwọn míì máa ń ṣiṣẹ́ níbi tá a ti ń kọ́lé, gbogbo wa la sì ń fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àtàwọn míì ló mú kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin bá a ṣe ń pésẹ̀ sípàdé tá a sì ń kópa nínú ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ̀ wá nígbà míì, a máa ń rí i dájú pé a lọ sípàdé. Táyà wa bá tiẹ̀ ń já, a ṣì máa ń dáhùn. Bákan náà, bá a tiẹ̀ láwọn ìṣòro tá à ń bá yí, ìyẹn ò ní ká má fún àwọn ará níṣìírí kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé. (Héb. 10:24, 25) Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ ńlá làwọn ará wa ń ṣe, a sì mọyì wọn gan-an! w21.01 10 ¶11
Wednesday, August 24
Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di agbéraga.—Gál. 5:26.
Kì í rọrùn fáwọn tó ń gbéra ga láti yin àwọn míì torí wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn máa yin àwọn. Wọ́n máa ń fi ara wọn wé àwọn míì, wọ́n sì gbà pé àwọn sàn ju àwọn míì lọ. Wọn kì í dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, wọn kì í sì í gbéṣẹ́ fún wọn. Nǹkan tírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń sọ ni pé, “Tó o bá fẹ́ kíṣẹ́ ẹ di ṣíṣe”—ìyẹn báwọn ṣe fẹ́—“àfi kó o ṣe é fúnra ẹ.” Agbéraga èèyàn máa ń fẹ́ kó jẹ́ pé òun lòun gbayì jù, ó sì máa ń jowú táwọn míì bá ṣe dáadáa jù ú lọ. Tá a bá rí i pé a ti fẹ́ máa gbéra ga, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà taratara pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ‘yí èrò inú wa pa dà’ kí ìwà burúkú yìí má bàa gbilẹ̀ nínú ọkàn wa. (Róòmù 12:2) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa! (Sm. 18:35) A rí bó ṣe ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bá àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ lò, a sì fẹ́ fara wé e. Yàtọ̀ síyẹn, a tún fẹ́ fara wé àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n fi ìrẹ̀lẹ̀ bá Ọlọ́run rìn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fún Jèhófà ní gbogbo ògo àti ọlá tó tọ́ sí i.—Ìfi. 4:11. w20.08 13 ¶19-20
Thursday, August 25
Àwọn tó [ṣègbéyàwó] máa ní ìpọ́njú nínú ara wọn.—1 Kọ́r. 7:28.
Jèhófà ló fi ìgbéyàwó jíǹkí wa, ẹ̀bùn tí ò lábùkù sì ni. Àmọ́, aláìpé làwa èèyàn. (1 Jòh. 1:8) Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi kìlọ̀ fún àwọn tọkọtaya pé wọ́n máa ní “ìpọ́njú nínú ara wọn.” Jèhófà fẹ́ káwọn ọkọ máa pèsè ohun tí ìdílé wọn nílò nípa tẹ̀mí àti nípa tara, kí wọ́n sì mú kára tù wọ́n. (1 Tím. 5:8) Síbẹ̀, ó yẹ kí àwọn arábìnrin tó ti ṣègbéyàwó máa wáyè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, kí wọ́n máa ronú lé ohun tí wọ́n kà, kí wọ́n sì máa gbàdúrà látọkàn wá. Àmọ́, ó lè má rọrùn nígbà míì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọwọ́ àwọn aya sábà máa ń dí, bó ti wù kó rí, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà fẹ́ kí gbogbo wa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun, ká má sì jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe náà jẹ́. (Ìṣe 17:27) Ká sòótọ́, ó máa gba ìsapá kí aya kan tó lè fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀ tó jẹ́ aláìpé. Àmọ́, ó máa rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá mọ ìdí tí Jèhófà fi sọ pé kó fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀, tó sì gbà bẹ́ẹ̀. w21.02 9 ¶3, 6-7
Friday, August 26
Ìgbàgbọ́ yín tí a dán wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó máa mú kí ẹ ní ìfaradà.—Jém. 1:3.
A lè fi àdánwò wé iná tí àwọn alágbẹ̀dẹ fi máa ń yọ́ irin. Lẹ́yìn tí wọ́n bá yọ irin náà kúrò nínú iná, tó sì tutù, á túbọ̀ lágbára. Lọ́nà kan náà, tá a bá fara da àdánwò, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára. Ìdí nìyẹn tí Jémíìsì fi sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeparí, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì máa ṣe ohun tó tọ́ nínú ohun gbogbo.” (Jém. 1:4) Bá a ṣe ń kíyè sí i pé ṣe làwọn àdánwò yẹn ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, àá túbọ̀ máa láyọ̀ bá a ṣe ń fara dà á. Nínú lẹ́tà tí Jémíìsì kọ, ó tún sọ àwọn nǹkan kan tó lè mú káyọ̀ wa pẹ̀dín. Ọ̀kan lára ẹ̀ ni pé a ò mọ ohun tó yẹ ká ṣe. Tá a bá ń kojú ìṣòro, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ohun táá múnú ẹ̀ dùn, táá ṣe àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láǹfààní, táá sì mú ká jẹ́ olóòótọ́. (Jer. 10:23) A nílò ọgbọ́n ká lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe àtohun tá a máa sọ fáwọn tó ń ta kò wá. Tá ò bá mọ ohun tó yẹ ká ṣe, ìrẹ̀wẹ̀sì lè bá wa, a sì lè má láyọ̀ mọ́. w21.02 28 ¶7-9
Saturday, August 27
Ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara yín látọkàn wá.—1 Pét. 1:22.
Tó bá di pé ká fi ìfẹ́ hàn, kò sí ẹlẹgbẹ́ Jèhófà, òun ló fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀. Ìfẹ́ tó ní sí wa jinlẹ̀ gan-an débi pé tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí i, kò sóhun tó máa yà wá kúrò nínú ìfẹ́ rẹ̀. (Róòmù 8:38, 39) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “jinlẹ̀” nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí gba pé kéèyàn sapá tàbí kó lo gbogbo okun rẹ̀. Nígbà míì, ó lè gba pé ká “sapá” tàbí “ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe” ká lè fìfẹ́ hàn sí ẹnì kan nínú ìjọ. Táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá, á dáa ká fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé “ẹ máa fara dà á fún ara yín nínú ìfẹ́, kí ẹ máa sapá lójú méjèèjì láti pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.” (Éfé. 4:1-3) A ò ní máa wá ibi tí àwọn ará wa kù sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ará wa wò wọ́n. (1 Sám. 16:7; Sm. 130:3) Kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa, pàápàá tá a bá mọ kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. Ó jọ pé irú ìṣòro yìí ni Yúódíà àti Síńtíkè ní. Torí náà, Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé “kí wọ́n ní èrò kan náà nínú Olúwa.”—Fílí. 4:2, 3. w21.01 22-23 ¶10-11
Sunday, August 28
Mo kọ̀wé sí ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, torí ẹ jẹ́ alágbára, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà nínú yín, ẹ sì ti ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.—1 Jòh. 2:14.
Inú àwọn ará máa ń dùn tí wọ́n bá ń rí i tí ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin ń ‘sin Jèhófà ní ìṣọ̀kan’ pẹ̀lú wọn! (Sef. 3:9) Inú wọn máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá rí i tẹ́ ẹ̀ ń fi ìtara àti gbogbo okun yín ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá gbé fún yín nínú ìjọ. Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé wọ́n mọyì yín gan-an. Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, ẹ fi sọ́kàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín, ó sì fọkàn tán yín. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa yọ̀ǹda ara wọn tinútinú. (Sm. 110:1-3) Ó mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ òun, o sì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn òun. Torí náà, máa ṣe sùúrù. Tó o bá sì ṣàṣìṣe, gba ìmọ̀ràn àti ìbáwí èyíkéyìí tí wọ́n bá fún ẹ torí àtọ̀dọ̀ Jèhófà ló ti wá. (Héb. 12:6) Yàtọ̀ síyẹn, ọwọ́ pàtàkì ni kó o fi mú iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún ẹ. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, máa ṣe ohun táá múnú Jèhófà Baba rẹ ọ̀run dùn nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe.—Òwe 27:11. w21.03 7 ¶17-18
Monday, August 29
Tí o bá rẹ̀wẹ̀sì lásìkò ìdààmú, agbára rẹ ò ní tó nǹkan.—Òwe 24:10, àlàyé ìsàlẹ̀.
Onírúurú nǹkan ló lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, ó lè jẹ́ ìṣòro ara ẹni tàbí àwọn nǹkan míì. Lára wọn ni àìpé wa, àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa àti àìsàn. A tún lè rẹ̀wẹ̀sì tí ọwọ́ wa ò bá tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù wá tàbí tí ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ò bá méso jáde. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè ro ara wa pin nítorí àìpé àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa. Kódà, ìyẹn lè mú ká ronú pé kì í ṣe irú wa ni Jèhófà máa jẹ́ kó wọnú ayé tuntun. Irú èrò yìí léwu gan-an. Bíbélì sọ pé “gbogbo èèyàn ti ṣẹ̀” àfi Jésù nìkan. (Róòmù 3:23) Àmọ́ o, kì í ṣe pé Baba wa ọ̀run ń wá ibi tá a kù sí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò retí pé ká jẹ́ ẹni pípé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ń mú sùúrù fún wa. Ó rí bá a ṣe ń sapá, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa, ká má sì ro ara wa pin.—Róòmù 7:18, 19. w20.12 22 ¶1-3
Tuesday, August 30
Tóò, ẹ̀yin ará, ẹ máa yọ̀, ẹ máa ṣe ìyípadà.—2 Kọ́r. 13:11.
Gbogbo wa pátá là ń rìnrìn àjò. Ibo là ń lọ? À ń lọ sínú ayé tuntun níbi tá a ti máa wà lábẹ́ àkóso Jèhófà. Ojoojúmọ́ là ń sapá láti máa rìn ní ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Àmọ́ bí Jésù ti sọ, ojú ọ̀nà yẹn há, ó sì ṣòro rìn. (Mát. 7:13, 14) Torí pé a jẹ́ aláìpé, ó rọrùn gan-an ká ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà yẹn. (Gál. 6:1) Tá ò bá fẹ́ kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè, a gbọ́dọ̀ ṣe tán láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nínú bá a ṣe ń ronú, bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ àti nínú ìwà wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé, “ẹ máa ṣe ìyípadà” tó yẹ. Kì í rọrùn fún wa láti mọ irú ẹni tá a jẹ́ nínú, ìdí sì ni pé ọkàn wa máa ń tàn wá jẹ. Ó sì lè mú kó ṣòro fún wa láti mọ ìgbésẹ̀ tó yẹ ká gbé. (Jer. 17:9) Ó rọrùn gan-an láti fi “èrò èké” tan ara wa jẹ. (Jém. 1:22) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ ara wa wò. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ nínú, ó sì máa ń jẹ́ ká mọ “ìrònú àti ohun tí ọkàn [wa] ń gbèrò.”—Héb. 4:12, 13. w20.11 18 ¶1-3
Wednesday, August 31
Nínú bíbu ọlá fún ara yín, ẹ mú ipò iwájú.—Róòmù 12:10.
Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tá a sì mọ̀wọ̀n ara wa, a máa láyọ̀. Kí nìdí? Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, inú wa máa dùn, a sì máa mọyì ohun táwọn míì bá ṣe fún wa. Àpẹẹrẹ kan nìgbà tí Jésù wo àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá sàn. Ẹ rántí pé ẹnì kan péré ló pa dà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù torí ó mọ̀ pé òun ò lè wo ara òun sàn láé. Ó ṣe kedere pé ọkùnrin yìí lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó mọyì ohun tí Jésù ṣe fún òun, ó sì yin Ọlọ́run lógo. (Lúùkù 17:11-19) Àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn máa ń ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì. Kí nìdí? Wọ́n gbà pé àwọn míì láwọn ànímọ́ tó dáa, wọ́n sì máa ń fọkàn tán wọn. Inú àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn máa ń dùn táwọn míì bá ṣàṣeyọrí, wọ́n sì máa ń yìn wọ́n tinútinú. w20.08 12 ¶17-18