October
Saturday, October 1
“Ta ló ti wá mọ èrò inú Jèhófà, kí ó lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́?” Àmọ́ àwa ní èrò inú Kristi.—1 Kọ́r. 2:16.
Tá a bá mọ Jésù dáadáa, àá máa ronú àá sì máa hùwà bíi tiẹ̀. Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ Jésù tá a sì ń ronú bíi tiẹ̀, okùn ọ̀rẹ́ wa á túbọ̀ máa lágbára. Báwo la ṣe lè fara wé Jésù? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Bí Jésù ṣe máa ran àwọn míì lọ́wọ́ ló jẹ ẹ́ lógún, kì í ṣe bó ṣe máa tẹ́ ara ẹ̀ lọ́rùn. (Mát. 20:28; Róòmù 15:1-3) Torí pé ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ ẹ́ lógún ló mú kó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ, ìyẹn náà ló sì mú kó máa dárí jini. Kì í bínú táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa ẹ̀. (Jòh. 1:46, 47) Kì í fi àṣìṣe téèyàn ṣe tipẹ́tipẹ́ hùwà sí i, kò sì ronú pé wọn ò lè yí pa dà. (1 Tím. 1:12-14) Jésù sọ pé: “Gbogbo èèyàn máa . . . mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.” (Jòh. 13:35) O ò ṣe bi ara ẹ pé, “Ṣé mò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ṣé mo sì ń wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi?” w20.04 22 ¶11
Sunday, October 2
Wọ́n máa sọ orúkọ mi di mímọ́.—Àìsá. 29:23.
Lóòótọ́ inú ayé táwọn èèyàn ti ń tàbùkù sí Jèhófà tí wọ́n sì ń bà á lórúkọ jẹ́ lò ń gbé, síbẹ̀ o lè jẹ́ káwọn míì mọ òótọ́ nípa Jèhófà, pé ẹni mímọ́ ni, ó jẹ́ olódodo, ẹni rere, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. O lè fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà lo fara mọ́. O lè jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé Ìjọba Jèhófà nìkan ló máa tẹ́ aráyé lọ́rùn, òun ló sì máa mú àlàáfíà àti ayọ̀ wá fún aráyé. (Sm. 37:9, 37; 146:5, 6, 10) Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, a sábà máa ń tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run, òótọ́ sì ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò burú láti kọ́ àwọn èèyàn ní òfin Ọlọ́run, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run, kí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Torí náà, ó yẹ ká máa tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ rere tí Jèhófà ní, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tó jẹ́. (Àìsá. 63:7) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn á nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n á sì máa ṣègbọràn sí i torí pé wọ́n fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí i. w20.06 6 ¶16; 7 ¶19
Monday, October 3
Ta ló fún èèyàn ní ẹnu . . . ? Ǹjẹ́ kì í ṣe èmi Jèhófà ni?—Ẹ́kís. 4:11.
Ọpọlọ àwa èèyàn ṣàrà ọ̀tọ̀, kódà àgbàyanu ni. Ìgbà tí ọmọ kan bá wà nínú ìyá rẹ̀ ni ọpọlọ rẹ̀ á ti wà létòletò, tí ọpọlọ náà á máa dàgbà díẹ̀díẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún sẹ́ẹ̀lì tuntun á sì máa rú yọ níṣẹ̀ẹ́jú kọ̀ọ̀kan. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fojú bù ú pé iṣan tó wà nínú ọpọlọ ẹnì kan tó ti dàgbà tó bílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún. Jèhófà fara balẹ̀ ṣètò àwọn iṣan ọpọlọ wa yìí lọ́nà àgbàyanu, tá a bá sì gbé e sórí òṣùwọ̀n ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó kílò kan ààbọ̀ (1.5 kg). Ọ̀kan lára ohun tó mú kí ọpọlọ wa ṣàrà ọ̀tọ̀ ni bá a ṣe ń sọ̀rọ̀. Gbogbo ìgbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ ni ọpọlọ wa máa ń darí àwọn iṣan bí ọgọ́rùn-ún tó wà ní ahọ́n, ọ̀fun, ètè, àgbọ̀n àti àyà wa. Àwọn iṣan náà sì gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ ní àsìkò tó yẹ gẹ́lẹ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ọ̀rọ̀ wa ò ní já geere. Bákan náà, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lọ́dún 2019 fi hàn pé, àwọn ọmọ jòjòló lè dá ohùn èèyàn mọ̀ kí wọ́n sì gbọ́ èdè tẹ́nì kan bá sọ sí wọn. Ìwádìí yìí jẹ́rìí sí i pé àtikékeré la ti ní agbára láti kọ́ èdè ká sì lóye ọ̀rọ̀. Kò sí àní-àní pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni bá a ṣe ń sọ̀rọ̀. w20.05 22-23 ¶8-9
Tuesday, October 4
Ó ń retí ìlú tó ní ìpìlẹ̀ tòótọ́, tí Ọlọ́run ṣètò, tó sì kọ́.—Héb. 11:10.
Tinútinú ni Ábúráhámù fi fi àwọn nǹkan amáyédẹrùn tó ń gbádùn nílùú Úrì sílẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ń retí “ìlú tó ní ìpìlẹ̀ tòótọ́.” (Héb. 11:8-10, 16) Ìjọba Ọlọ́run ni ìlú tí Ábúráhámù ń retí, Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ló sì para pọ̀ jẹ́ ìlú náà. Pọ́ọ̀lù pe Ìjọba yìí ní “ìlú Ọlọ́run alààyè, Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run.” (Héb. 12:22; Ìfi. 5:8-10; 14:1) Ìjọba yìí kan náà ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún nígbà tó gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí ìfẹ́ Ọlọ́run sì ṣẹ ní ayé bíi ti ọ̀run. (Mát. 6:10) Ṣé Ábúráhámù mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa rí? Rárá. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ọdún ni ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fi jẹ́ “àṣírí mímọ́.” (Éfé. 1:8-10; Kól. 1:26, 27) Àmọ́ Ábúráhámù mọ̀ pé àwọn kan lára àtọmọdọ́mọ òun máa di ọba torí pé Jèhófà dìídì sọ bẹ́ẹ̀ fún un.—Jẹ́n. 17:1, 2, 6. w20.08 2-3 ¶2-4
Wednesday, October 5
Ẹ máa rìn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú [Olúwa], kí ẹ ta gbòǹgbò, kí ẹ sì máa dàgbà nínú rẹ̀, kí ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.—Kól. 2:6, 7.
A gbọ́dọ̀ sá fún ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà pátápátá. Àtìgbà tí ìjọ Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ ni Sátánì ti ń lo àwọn ẹlẹ́tàn láti ṣi àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́nà. Torí náà, ó yẹ ká mọ ìyàtọ̀ láàárín irọ́ àti òótọ́. Àwọn tó kórìíra wa lè lo Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí ìkànnì àjọlò láti tan irọ́ kálẹ̀ nípa wa kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà má bàa lágbára mọ́, kí ìfẹ́ tá a ní sáwọn ará wa sì dín kù. Àmọ́ má gbàgbé o, Sátánì ló wà nídìí irú àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀, torí náà má gba irú ẹ̀ láyè láé! (1 Jòh. 4:1, 6; Ìfi. 12:9) Sátánì fẹ́ ká máa ṣiyèméjì nípa Jèhófà, torí náà tá a bá fẹ́ borí, a gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù àtàwọn ohun tó máa ṣe kí ìfẹ́ Ọlọ́run lè ṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, a tún gbọ́dọ̀ fọkàn tán àwọn tí Jèhófà ń lò láti darí ètò rẹ̀ lónìí. (Mát. 24:45-47) Tá a bá fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, a gbọ́dọ̀ máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Ìgbà yẹn la máa dà bí igi tó ta gbòǹgbò dáadáa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó jọ èyí nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. w20.07 23-24 ¶11-12
Thursday, October 6
Ohun tí ó bá hàn síta ni èèyàn ń rí, ṣùgbọ́n Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.—1 Sám. 16:7.
Torí pé aláìpé ni wá, gbogbo wa la máa ń fẹ́ fi ìrísí ojú tàbí ohun míì dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. (Jòh. 7:24) Àmọ́, bí wọ́n ṣe máa ń sọ, a kì í gbé òkèèrè mọ dídùn ọbẹ̀, ó dìgbà tá a bá sún mọ́ ẹnì kan ká tó lè mọ ìṣe rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká ṣe àkàwé ẹ̀ pẹ̀lú dókítà kan tó mọṣẹ́ gan-an. Nǹkan mélòó ló lè sọ pé òun mọ̀ nípa aláìsàn kan tó wá sọ́dọ̀ ẹ̀ kó tó yẹ̀ ẹ́ wò? Kó tó lè sọ irú àìsàn tó ń ṣe é, ó gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí i dáadáa, kó mọ irú àìsàn tó máa ń ṣe é tẹ́lẹ̀, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹ̀ àtàwọn nǹkan míì táá jẹ́ kó mọ irú àìsàn tó ń ṣe é gan-an. Kódà, dókítà náà lè ní kí onítọ̀hún lọ ya àwòrán ibi tó ń dùn ún tàbí lédè míì kó lọ ṣe X-ray, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ dókítà náà lè fi ẹ̀fọ́rí pe inú rírun. Lọ́nà kan náà, ìwọ̀nba la lè sọ nípa àwọn ará wa tó bá jẹ́ pé ìrísí wọn nìkan là ń wò. Torí náà, irú ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú gan-an ló yẹ ká máa wò. Àmọ́ o, bó ti wù ká gbìyànjú tó, a ò lè rí ohun tó wà lọ́kàn wọn. Síbẹ̀, a lè sapá láti fara wé Jèhófà. Ó máa ń tẹ́tí sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó máa ń wo ipò àtilẹ̀wá wọn mọ́ wọn lára, ó sì mọ ohun tó mú kí wọ́n máa ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe. Bákan náà, ó máa ń gba tiwọn rò. w20.04 14-15 ¶1-3
Friday, October 7
Ronú lọ́nà tó fi hàn pé [o] láròjinlẹ̀.—Róòmù 12:3.
Ó yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ torí pé àwọn agbéraga ò “láròjinlẹ̀.” Àwọn agbéraga máa ń fọ́nnu, wọ́n sì máa ń bá àwọn míì díje. Ìrònú wọn àti ìwà wọn máa ń mú kí wọ́n ṣàkóbá fún ara wọn àtàwọn míì. Tí wọn ò bá yí pa dà, Sátánì máa fọ́ ojú inú wọn, á sì sọ wọ́n dìbàjẹ́. (2 Kọ́r. 4:4; 11:3) Àmọ́ onírẹ̀lẹ̀ èèyàn máa ń ní àròjinlẹ̀. Kì í ro ara ẹ̀ pin, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ torí ó mọ̀ pé àwọn míì sàn ju òun lọ lónírúurú ọ̀nà. (Fílí. 2:3) Bákan náà, ó mọ̀ pé “Ọlọ́run dojú ìjà kọ àwọn agbéraga, àmọ́ ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (1 Pét. 5:5) Àwọn tó láròjinlẹ̀ ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa sọ wọ́n di ọ̀tá Jèhófà. Tá ò bá fẹ́ di agbéraga, a gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò tó ní ká “bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, [ká] sì fi ìwà tuntun wọ ara [wa] láṣọ.” Á ṣeé ṣe tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.—Kól. 3:9, 10; 1 Pét. 2:21. w20.07 7 ¶16-17
Saturday, October 8
Ara jẹ́ ọ̀kan àmọ́ ó ní ẹ̀yà púpọ̀.—1 Kọ́r. 12:12.
Àǹfààní ńlá la ní pé a wà nínú ètò Jèhófà. Inú Párádísè tẹ̀mí la wà yìí, láàárín àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà, tí wọ́n sì ń láyọ̀. Àmọ́ ìbéèrè kan ni pé, ṣé gbogbo wa la wúlò nínú ìjọ Ọlọ́run? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìjọ wé ara èèyàn. Bákan náà, ó fi àwọn tó wà nínú ìjọ wé ẹ̀yà ara. (Róòmù 12:4-8; 1 Kọ́r. 12:12-27; Éfé. 4:16) Ẹ̀kọ́ kan tá a rí kọ́ nínú àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù lò ni pé gbogbo wa pátá la ní ojúṣe pàtàkì nínú ìjọ Ọlọ́run. Ohun tí Pọ́ọ̀lù fi bẹ̀rẹ̀ àpèjúwe náà ni pé: “Bí ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara ṣe wà nínú ara kan, àmọ́ tí gbogbo ẹ̀yà ara kì í ṣe iṣẹ́ kan náà, bẹ́ẹ̀ ni àwa, bí a tiẹ̀ pọ̀, a jẹ́ ara kan ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, àmọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a jẹ́ ẹ̀yà ara fún ẹnì kejì wa.” (Róòmù 12:4, 5) Kí ni Pọ́ọ̀lù ń sọ gan-an? Kókó náà ni pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ló ní ojúṣe tiẹ̀ nínú ìjọ, kò sì sí èyí tí kò ṣe pàtàkì nínú wọn. w20.08 20 ¶1-2; 21 ¶4
Sunday, October 9
Jèhófà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Báwo lo ṣe máa ṣe é?”—1 Ọba 22:21.
Ẹ̀yin òbí, báwo lẹ ṣe lè fi hàn pé ẹ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Jèhófà? Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín sọ èrò wọn nípa bí ẹ ṣe lè ṣe àwọn nǹkan nínú ilé. Tó bá sì bọ́gbọ́n mu, ẹ ṣe ohun tí wọ́n sọ. Jèhófà tún fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa ni ti pé ó máa ń mú sùúrù. Bí àpẹẹrẹ, kì í bínú táwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ bá fìrẹ̀lẹ̀ béèrè pé kí nìdí tó fi ṣe ìpinnu tó ṣe. Ìgbà kan wà tó fara balẹ̀ tẹ́tí sí Ábúráhámù nígbà tó ń béèrè pé kí nìdí tó fi fẹ́ pa Sódómù àti Gòmórà run. (Jẹ́n. 18:22-33) Ṣé ẹ rántí ohun tí Jèhófà ṣe nígbà tí Sérà rẹ́rìn-ín lẹ́yìn tó gbọ́ pé òun máa lóyún ní ọjọ́ ogbó òun? Jèhófà ò bínú sí i, kò sì kàn án lábùkù. (Jẹ́n. 18:10-14) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló pọ́n Sérà lé. Ẹ̀yin òbí àtẹ̀yin alàgbà, kí lẹ rí kọ́ lára Jèhófà? Báwo ló ṣe máa ń rí lára yín tí àwọn ọmọ yín tàbí àwọn akéde inú ìjọ bá béèrè ìdí tẹ́ ẹ fi ṣe ohun tẹ́ ẹ ṣe? Ṣé kì í ṣe pé ẹ máa ń jájú mọ́ wọn? Àbí ṣe lẹ máa ń fara balẹ̀ gbọ́ tẹnu wọn? Inú àwọn tó wà nínú ìdílé àtàwọn tó wà nínú ìjọ máa dùn tí àwọn tó wà nípò àṣẹ bá ń fara wé Jèhófà. w20.08 10 ¶7-9
Monday, October 10
À ń sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.—2 Kọ́r. 12:9.
Nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà, ó ṣeé ṣe kó máa yá wa lára láti gba ìrànlọ́wọ́ táwọn míì fẹ́ ṣe fún wa torí a mọ̀ pé ìmọ̀ Bíbélì tá a ní ò pọ̀. (1 Kọ́r. 3:1, 2) Àmọ́ ní báyìí ńkọ́? Tó bá ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà tá a sì ti ní ìrírí gan-an, ó lè má rọrùn fún wa láti gbà pé kí ẹlòmíì ràn wá lọ́wọ́ pàápàá tí ẹni náà ò bá tíì pẹ́ tó wa nínú òtítọ́. Àmọ́ ká má gbàgbé pé àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni Jèhófà máa ń lò láti fún wa lókun. (Róòmù 1:11, 12) Torí náà, tá a bá fẹ́ kí Jèhófà fún wa lókun, àfi ká jẹ́ káwọn ará wa ràn wá lọ́wọ́. Kì í ṣe agbára téèyàn ní, ìwé tó kà, bó ṣe lówó tó tàbí ibi tó ti wá ló máa jẹ́ kó ṣàṣeyọrí. Dípò bẹ́ẹ̀, èèyàn gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kó sì gbára lé Jèhófà. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa tẹ̀ síwájú. Lọ́nà wo? Ká máa gbára lé Jèhófà, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì, ká sì gbà káwọn Kristẹni bíi tiwa ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa sọ wá di alágbára láìka pé a jẹ́ aláìlera sí tàbí pé a láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tá à ń bá yí! w20.07 14 ¶2; 19 ¶18-19
Tuesday, October 11
Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín máa ṣiṣẹ́ kára bẹ́ẹ̀ . . . kí ẹ má bàa máa lọ́ra, àmọ́ kí ẹ lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tí ìgbàgbọ́ àti sùúrù mú kí wọ́n jogún àwọn ìlérí náà.—Héb. 6:11, 12.
Ó sábà máa ń ṣòro láti mú sùúrù tá a bá ń wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Àmọ́, ìlànà tó wà nínú Oníwàásù 3:1, 7 lè ràn wá lọ́wọ́. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Ohun gbogbo ni àkókò wà fún . . . Ìgbà dídákẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.” Láìsọ̀rọ̀, a lè jẹ́ kí ìwà wa wàásù fún wọn, síbẹ̀ ká wà lójúfò láti bá wọn sọ̀rọ̀ nígbà tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ. (1 Pét. 3:1, 2) A gbọ́dọ̀ mú sùúrù fún gbogbo èèyàn títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wa tá a bá ń wàásù tá a sì ń kọ́ni. A lè kọ́ bá a ṣe lè mú sùúrù látinú àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ kan nínú Bíbélì àti lóde òní. Bí àpẹẹrẹ, ó wu Hábákúkù gan-an pé kí ìwà burúkú tètè dópin, síbẹ̀ ó pinnu pé: “Ibi tí mo ti ń ṣe olùṣọ́ ni èmi yóò dúró sí.” (Háb. 2:1) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ pé òun máa “parí” iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun. Síbẹ̀, ó mú sùúrù bó ṣe ń “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.”—Ìṣe 20:24. w20.09 11-12 ¶12-14
Wednesday, October 12
[Jésù] kò ronú rárá láti já nǹkan gbà, ìyẹn, pé kó bá Ọlọ́run dọ́gba.—Fílí. 2:6.
Lẹ́yìn Jèhófà, Jésù ló lágbára jù láyé àti lọ́run, síbẹ̀ kò ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Bíi ti Jésù, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ń mú kí ìfẹ́ túbọ̀ gbilẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run. (Lúùkù 9:48; Jòh. 13:35) Táwọn ìṣòro kan bá wáyé nínú ìjọ, tó o sì ronú pé àwọn alàgbà ò bójú tó ọ̀rọ̀ náà bó ṣe yẹ, kí lo máa ṣe? Dípò tí wàá fi máa ráhùn, ṣe ni kó o fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn, kó o sì kọ́wọ́ ti ìpinnu táwọn alábòójútó bá ṣe. (Héb. 13:17) Kó lè rọrùn fún ẹ, á dáa kó o bi ara ẹ pé: ‘Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ náà lágbára tó? Tó bá sì yẹ kí wọ́n bójú tó o, ṣé àsìkò tó yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ nìyí? Ṣé èmi ló yẹ kí n pe àfiyèsí wọn sí i? Ká sòótọ́, ṣé àlàáfíà ìjọ ni mò ń wá, àbí mo fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé mi gẹ̀gẹ̀?’ Jèhófà mọyì ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wa ju ẹ̀bùn èyíkéyìí tá a ní lọ, ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ara wa sì ṣe pàtàkì sí i ju ká mọ nǹkan ṣe lọ. Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o lè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Tó o bá ń fìrẹ̀lẹ̀ sin Jèhófà, wàá fi kún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ.—Éfé. 4:2, 3. w20.07 4-5 ¶9-11
Thursday, October 13
Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù! Ẹ lọ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi.”—Mát. 28:10.
Jésù mọyì àwọn obìnrin tó ń tẹ̀ lé e bí wọ́n ṣe “ń fi àwọn ohun ìní wọn ṣe ìránṣẹ́” fún òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Lúùkù 8:1-3) Jésù kọ́ wọn láwọn òtítọ́ tó jinlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun máa kú, òun sì máa jíǹde. (Lúùkù 24:5-8) Ó múra àwọn obìnrin yìí sílẹ̀ fún inúnibíni tí wọ́n máa kojú bó ṣe ṣe fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀. (Máàkù 9:30-32; 10:32-34) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn àpọ́sítélì pátá ló sá lọ nígbà tí wọ́n mú Jésù, àwọn kan lára àwọn obìnrin yẹn wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ nígbà tó wà lórí òpó igi oró. (Mát. 26:56; Máàkù 15:40, 41) Àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ló kọ́kọ́ rí i lẹ́yìn tó jíǹde. Àwọn obìnrin yẹn ló rán pé kí wọ́n lọ sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé òun ti jíǹde. (Mát. 28:5, 9, 10) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Kristẹni, ó ṣeé ṣe káwọn obìnrin náà wà níbẹ̀ nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn náà sọ èdè àjèjì lọ́nà ìyanu, wọ́n sì kéde “àwọn ohun àgbàyanu Ọlọ́run.”—Ìṣe 1:14; 2:2-4, 11. w20.09 23 ¶11-12
Friday, October 14
Máa kíyè sí ara rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ nígbà gbogbo.—1 Tím. 4:16.
Iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà ni iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Báwo la ṣe mọ̀? Nígbà tí Jésù ń pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú Mátíù 28:19, 20, ó sọ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.” Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn ṣèrìbọmi? Ìdí ni pé téèyàn bá máa rí ìgbàlà, àfi kó ṣèrìbọmi. Ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi gbọ́dọ̀ gbà pé torí pé Jésù kú ó sì jíǹde nìkan ni aráyé á fi rí ìgbàlà. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi sọ fáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé: “Ìrìbọmi [ló] tún ń gbà yín là báyìí . . . nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi.” (1 Pét. 3:21) Torí náà, bí ọmọ ẹ̀yìn kan bá ṣèrìbọmi, á nírètí àtiwà láàyè títí láé. Ká tó lè sọni dọmọ ẹ̀yìn, a gbọ́dọ̀ máa lo “ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó dáa.” (2 Tím. 4:1, 2) Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù pàṣẹ fún wa pé: “Ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn . . . , ẹ máa kọ́ wọn.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ká “rí i pé [a] ò jáwọ́” nínú iṣẹ́ náà, ‘torí tí a bá ń ṣe é, àá lè gba ara wa àti àwọn tó ń fetí sí wa là.’ w20.10 14 ¶1-2
Saturday, October 15
Láti ìsinsìnyí lọ, wàá máa mú àwọn èèyàn láàyè.—Lúùkù 5:10.
Pétérù kọ́ bí wọ́n ṣe ń sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn, ó sì nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ náà. Jèhófà ràn án lọ́wọ́ débi pé ó já fáfá gan-an nínú iṣẹ́ náà. (Ìṣe 2:14, 41) Ìdí pàtàkì tá a fi ń wàásù ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó máa yá wa lára láti sọ̀rọ̀ ẹ̀ fáwọn míì bí a tiẹ̀ ń ronú pé a ò kúnjú ìwọ̀n láti wàásù. Nígbà tí Jésù pe Pétérù pé kó wá di apẹja èèyàn, ó sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù mọ́.” (Lúùkù 5:8-11) Kì í ṣe ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tóun bá dọmọ ẹ̀yìn ló ń ba Pétérù lẹ́rù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó bà á lẹ́rù ni bí Jésù ṣe mú kí wọ́n pa ẹja rẹpẹtẹ lọ́nà ìyanu, ìyẹn sì mú kó ronú pé òun ò yẹ lẹ́ni tó ń bá Jésù ṣiṣẹ́. Lọ́wọ́ kejì, ẹ̀rù lè máa bà ẹ́ torí àwọn nǹkan tó o gbọ́dọ̀ ṣe tó o bá fẹ́ dọmọ ẹ̀yìn Jésù. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe ohun táá mú kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Jésù àtàwọn èèyàn, ìyẹn á sì mú kó túbọ̀ yá ẹ lára láti di akéde Ìjọba Ọlọ́run.—Mát. 22:37, 39; Jòh. 14:15. w20.09 3 ¶4-5
Sunday, October 16
Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn.—Mát. 28:19, 20.
Tayọ̀tayọ̀ la fi ń lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa láti wá “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ìṣe 13:48) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Jésù sọ pé: “Oúnjẹ mi ni pé kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi, kí n sì parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 4:34; 17:4) Ohun tí àwa náà pinnu láti ṣe nìyẹn. A ti pinnu láti parí iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa. (Jòh. 20:21) A sì fẹ́ kí àwọn míì dara pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ yìí títí kan àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́, ká sì jọ fara dà á títí dópin. (Mát. 24:13) Òótọ́ ni pé kò rọrùn láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa yìí, àmọ́ àwa nìkan kọ́ la máa ṣiṣẹ́ náà. Jésù ṣèlérí pé òun máa wà pẹ̀lú wa. Bíbélì sọ pé a jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run,” a sì ń bá Kristi ṣiṣẹ́ bá a ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. (1 Kọ́r. 3:9; 2 Kọ́r. 2:17) Torí náà, a lè ṣe iṣẹ́ yìí ní àṣeyọrí. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà fún wa ní àǹfààní láti ṣe iṣẹ́ yìí, ká sì ran àwọn míì lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀!—Fílí. 4:13. w20.11 7 ¶19-20
Monday, October 17
Ọgbọ́n Jésù wá ń pọ̀ sí i, ó ń dàgbà sí i, ó sì ń rí ojúure Ọlọ́run àti èèyàn.—Lúùkù 2:52.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ìpinnu táwọn òbí bá ṣe máa ń nípa lórí àwọn ọmọ wọn jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Táwọn òbí bá ṣe ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu, ó lè fa ìṣòro fáwọn ọmọ wọn. Àmọ́ tí wọ́n bá ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, wọ́n á mú kó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ wọn láti yan ìgbésí ayé tó dáa jù. Kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, àwọn ọmọ náà gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Ìpinnu tó dáa jù tẹ́nì kan lè ṣe ni pé kó sin Jèhófà Baba wa ọ̀run. (Sm. 73:28) Ohun táwọn òbí Jésù fẹ́ ni pé káwọn ọmọ wọn sin Jèhófà, àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe sì fi hàn bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 2:40, 41, 52) Jésù náà ṣe àwọn ìpinnu tó jẹ́ kó lè ṣe àwọn ohun tí Jèhófà tìtorí ẹ̀ rán an wá sáyé. (Mát. 4:1-10) Bí Jésù ṣe ń dàgbà, ó fi hàn pé òun jẹ́ onínúure, adúróṣinṣin àti onígboyà. Irú ọmọ àmúyangàn bẹ́ẹ̀ làwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sì máa fẹ́ láti ní. w20.10 26 ¶1-2
Tuesday, October 18
Ọ̀ọ́kán tààrà ni kí ojú rẹ máa wò.—Òwe 4:25.
Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ yìí. Arábìnrin àgbàlagbà kan ń ronú lórí ohun rere tó fi ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fún un báyìí, ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe fún Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:58) Ojoojúmọ́ ló máa ń fojú inú wo ìgbà tí òun àtàwọn èèyàn ẹ̀ á jọ máa gbádùn nínú ayé tuntun. Arábìnrin míì rántí ohun tẹ́nì kan nínú ìjọ ṣe sí i tó dùn ún, àmọ́ ó pinnu pé òun máa gbọ́rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. (Kól. 3:13) Arákùnrin kan rántí àwọn àṣìṣe tó ti ṣe sẹ́yìn, àmọ́ ó wá pinnu pé òun á máa fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà láti ìsinsìnyí lọ. (Sm. 51:10) Kí lohun tó jọra nínú àpẹẹrẹ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí? Gbogbo wọn ló rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn sẹ́yìn, àmọ́ kì í ṣèyẹn ni wọ́n ń rò ṣáá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọjọ́ iwájú ni wọ́n “tẹjú mọ́.” Kí nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì? Jẹ́ ká wò ó báyìí, kí lo rò pé ó lè ṣẹlẹ̀ tẹ́nì kan bá ń wẹ̀yìn ṣáá dípò kó kọjú síbi tó ń lọ? Ó lè fẹsẹ̀ kọ, kó sì ṣubú. Lọ́nà kan náà, tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tá a ti ṣe sẹ́yìn tàbí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí wa sẹ́yìn nìkan là ń rò, a ò ní lè tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.—Lúùkù 9:62. w20.11 24 ¶1-3
Wednesday, October 19
Ó wò ó tẹ̀gàntẹ̀gàn.—1 Sám. 17:42.
Lójú Gòláyátì tó jẹ́ òmìrán, ṣe ni Dáfídì dà bí èèrà. Ó ṣe tán, Gòláyátì rí fàkìàfakia, ó di ìhámọ́ra ogun, ó sì jẹ́ akínkanjú lójú ogun. Lọ́wọ́ kejì, Dáfídì dà bí ọmọ kékeré kan tí ò nírìírí. Bí nǹkan ṣe rí fún Dáfídì yìí mú kó gbára lé Jèhófà. Torí pé ó gbára lé Jèhófà, Jèhófà fún un lókun, ó sì ṣẹ́gun Gòláyátì. (1 Sám. 17:41-45, 50) Dáfídì tún kojú ìṣòro míì tó lè mú kó máa wo ara rẹ̀ bíi pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. Tọkàntọkàn ló fi ń sin Sọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì tí Jèhófà yàn. Níbẹ̀rẹ̀ Ọba Sọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ Dáfídì. Àmọ́ nígbà tó yá, ìgbéraga mú kí Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú ẹ̀. Sọ́ọ̀lù mú kí nǹkan nira fún Dáfídì, kódà ó fẹ́ pa á. (1 Sám. 18:6-9, 29; 19:9-11) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọba Sọ́ọ̀lù hùwà àìdáa sí Dáfídì, Dáfídì ṣì ń bọ̀wọ̀ fún un torí pé ọba tí Jèhófà yàn ni. (1 Sám. 24:6) Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa fún òun lókun tóun á fi fara da ìṣòro náà.—Sm. 18:1, àkọlé. w20.07 17 ¶11-13
Thursday, October 20
Ní àkókò òpin, ọba gúúsù máa kọ lu [ọba àríwá].—Dán. 11:40.
Apá tó pọ̀ jù lára àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọba àríwá àti ọba gúúsù ló ti nímùúṣẹ, ìyẹn sì jẹ́ kó dá wa lójú pé apá tó ṣẹ́ kù lára ẹ̀ náà máa ṣẹ láìsí tàbí ṣùgbọ́n. Ká lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì orí kọkànlá (11), ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn ìjọba àtàwọn alákòóso tí wọ́n ní ohun kan pàtó tí wọ́n ṣe sí àwọn èèyàn Ọlọ́run nìkan ni àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn tó wà láyé, àwọn ni ìjọba ayé sábà máa ń dájú sọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun kan ṣoṣo tó gba Sátánì àti ayé burúkú yìí lọ́kàn ni bí wọ́n ṣe máa run àwọn tó ń sin Jèhófà tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (Jẹ́n. 3:15; Ìfi. 11:7; 12:17) Ohun míì tó yẹ ká fi sọ́kàn ni pé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì gbọ́dọ̀ bá àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tó wà nínú Bíbélì mu. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ká tó lè ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì, ó ṣe pàtàkì ká wo àwọn apá míì nínú Ìwé Mímọ́. w20.05 2 ¶1-2
Friday, October 21
Báwo ni àwọn òkú ṣe máa jíǹde? Bẹ́ẹ̀ ni, irú ara wo ni wọ́n ń gbé bọ̀?—1 Kọ́r. 15:35.
Onírúurú èrò làwọn èèyàn ní nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú. Àmọ́ kí ni Bíbélì sọ? Tẹ́nì kan bá kú, ara ẹ̀ máa jẹrà. Àmọ́, Ẹni tó dá ayé àtọ̀run lè jí ẹni náà dìde kó sì fún un ní ara tuntun. (Jẹ́n. 1:1; 2:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo àpèjúwe kan láti jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe ara tó ti jẹrà yẹn ni Ọlọ́run máa fún ẹni náà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ “hóró” ọkà kan péré téèyàn gbìn. Tá a bá gbin hóró ọkà, á kọ́kọ́ jẹrà, lẹ́yìn náà á mú irúgbìn tuntun jáde. Irúgbìn tuntun yìí máa yàtọ̀ sí hóró kékeré tá a gbìn tẹ́lẹ̀. Àpèjúwe yìí ni Pọ́ọ̀lù lò láti jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa fún ẹni tó jíǹde náà ní “ara bí ó ṣe wù ú.” Pọ́ọ̀lù tún sọ pé “àwọn ohun tó wà ní ọ̀run ní ara tiwọn, àwọn tó wà ní ayé sì ní tiwọn.” Kí ló ní lọ́kàn? Ara tó ṣeé fojú rí làwa tí à ń gbé láyé ní, àmọ́ ara ti ẹ̀mí làwọn tó wà lọ́run ní bíi tàwọn áńgẹ́lì.—1 Kọ́r. 15:36-41. w20.12 9-10 ¶7-9
Saturday, October 22
Ìgbà wo ni mi ò ní dààmú mọ́, tí ẹ̀dùn ọkàn mi ojoojúmọ́ á sì dópin?—Sm. 13:2.
Gbogbo wa la fẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ kí ayé wa sì dùn. A kì í fẹ́ kí ohunkóhun kó wa lọ́kàn sókè rárá. Àmọ́ nígbà míì, ìṣòro lè mu wá lómi débi tá a fi máa béèrè irú ìbéèrè tí Ọba Dáfídì bi Jèhófà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Àwọn nǹkan kan wà tó lè mú ká máa ṣàníyàn, kò sì sóhun tá a lè ṣe sí i. Bí àpẹẹrẹ, kò sóhun tá a lè ṣe sí bí owó oúnjẹ, aṣọ àti ilé ṣe ń ga sí i lọ́dọọdún. Yàtọ̀ síyẹn, a ò lè pinnu iye ìgbà táwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ ilé ìwé wa máa fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ wá. Bákan náà, a ò lè dá ìwà ọ̀daràn dúró ní àdúgbò wa. Ìdí tá a fi ń kojú àwọn ìṣòro yìí ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Sátánì tó jẹ́ ọlọ́run ayé yìí mọ̀ pé àwọn kan máa jẹ́ kí “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí” gbà wọ́n lọ́kàn débi pé wọn ò ní rí ti Ọlọ́run rò. (Mát. 13:22; 1 Jòh. 5:19) Abájọ tí ìṣòro fi kúnnú ayé yìí! w21.01 2 ¶1, 3
Sunday, October 23
Gbogbo ẹni tó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apààyàn, ẹ sì mọ̀ pé kò sí apààyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun ṣì wà nínú rẹ̀.—1 Jòh. 3:15.
Àpọ́sítélì Jòhánù gbà wá níyànjú pé ká má ṣe kórìíra àwọn ará wa. Tá ò bá fi ìmọ̀ràn yìí sílò, Èṣù lè rí wa mú. (1 Jòh. 2:11) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn kan nìyẹn ní ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní S.K. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Sátánì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú káwọn ará kórìíra ara wọn, kí wọ́n sì kẹ̀yìn síra wọn. Nígbà tí Jòhánù fi máa kọ àwọn lẹ́tà rẹ̀, àwọn tó nírú ẹ̀mí tí Sátánì ní ti yọ́ wọnú ìjọ. Àpẹẹrẹ kan ni ti Díótíréfè tó ń dá ìpínyà sílẹ̀ nínú ìjọ. (3 Jòh. 9, 10) Kì í bọ̀wọ̀ fún àwọn aṣojú tí ìgbìmọ̀ olùdarí rán wá. Ó kórìíra àwọn tó ń gba àwọn aṣojú yẹn lálejò, ó sì fẹ́ lé wọn kúrò nínú ìjọ. Ẹ ò rí i pé ó jọra ẹ̀ lójú gan-an! Títí dòní ni Sátánì ṣì ń gbìyànjú láti kẹ̀yìn àwa èèyàn Jèhófà síra wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun mú ká kórìíra àwọn ará wa. w21.01 11 ¶14
Monday, October 24
Nígbà tí wọ́n bá jẹ́rìí tán, ẹranko [náà] . . . máa bá wọn jagun, ó máa ṣẹ́gun wọn, ó sì máa pa wọ́n.—Ìfi. 11:7.
Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ìjọba ilẹ̀ Jámánì àti ti Gẹ̀ẹ́sì ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run torí pé wọn ò dá sí ọ̀rọ̀ ogun. Bákan náà, ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ju àwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run sẹ́wọ̀n. Èyí ló mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìfihàn 11:7-10 ṣẹ. Nígbà tó yá, ìyẹn lẹ́yìn ọdún 1930, pàápàá nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ọba àríwá fayé ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lára gan-an. Hitler àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ fòfin de iṣẹ́ táwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣe. Àwọn ọ̀tá yìí pa àwọn bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ lára àwọn èèyàn Jèhófà, wọ́n sì rán ẹgbẹẹgbẹ̀rún míì lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ọba àríwá ‘sọ ibi mímọ́ di aláìmọ́, ó sì mú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo kúrò’ ní ti pé ó jẹ́ kó nira fáwọn èèyàn Jèhófà láti máa yìn ín kí wọ́n sì máa kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba. (Dán. 11:30b, 31a) Kódà, Hitler tó jẹ́ aṣáájú ìjọba Násì lérí pé òun máa pa gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà run ráúráú nílẹ̀ Jámánì. w20.05 6 ¶12-13
Tuesday, October 25
Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín. Nínú bíbu ọlá fún ara yín, ẹ mú ipò iwájú.—Róòmù 12:10.
Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ dénú, a ò ní máa bá ara wa díje. Ẹ rántí pé Jónátánì ò jowú Dáfídì, bẹ́ẹ̀ sì ni kò wò ó bíi pé ó ń bá òun du ipò ọba. (1 Sám. 20:42) Á dáa kí gbogbo wa fìwà jọ Jónátánì, ká má ṣe máa jowú àwọn ará wa nítorí ẹ̀bùn tí wọ́n ní. Kàkà bẹ́ẹ̀, ká fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé: “Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.” (Fílí. 2:3) Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé kò sẹ́ni tí ò wúlò nínú ìjọ. Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tá ò sì jọ ara wa lójú, àá mọyì ẹ̀bùn táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní, àá sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. (1 Kọ́r. 12:21-25) Tá a bá ń fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sí ara wa lẹ́nì kìíní kejì, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan á túbọ̀ gbilẹ̀ láàárín àwa èèyàn Jèhófà. Bákan náà, bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn jẹ́ ká fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni wá, ìyẹn sì ń jẹ́ káwọn olóòótọ́ ọkàn lè wá jọ́sìn Jèhófà. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, à ń fògo fún Jèhófà “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 Kọ́r. 1:3. w21.01 24 ¶14; 25 ¶16
Wednesday, October 26
Torí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, . . . ni ayé ṣe kórìíra yín.—Jòh. 15:19.
Lónìí, àwọn èèyàn ń fojú burúkú wo àwa èèyàn Jèhófà, wọ́n gbà pé a ò ní làákàyè a ò sì já mọ́ nǹkan kan. Kí nìdí? Ìdí ni pé a kì í hùwà bí àwọn èèyàn ayé. A lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a máa ń hùwà pẹ̀lẹ́, a sì máa ń pa òfin mọ́. Àmọ́ ẹ̀mí ìgbéraga, ìjọra-ẹni-lójú àti ìwà ọ̀tẹ̀ ni ayé ń gbé lárugẹ. Bákan náà, a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, a kì í sì í dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ológun èyíkéyìí. Torí pé a yàtọ̀ pátápátá sáwọn èèyàn ayé, wọ́n gbà pé a ò já mọ́ nǹkan kan. (Róòmù 12:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ń fojú burúkú wò wá, Jèhófà ń gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe nípasẹ̀ wa. Bí àpẹẹrẹ, ju ti ìgbàkigbà rí lọ, Jèhófà ń mú ká wàásù ìhìn rere níbi gbogbo láyé. Àwa èèyàn Jèhófà là ń tẹ ìwé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ tí wọ́n sì ń pín kiri jù lọ láyé. Yàtọ̀ síyẹn, à ń fi Bíbélì tún ìgbésí ayé àìmọye èèyàn ṣe. Kò sí àní-àní pé Jèhófà ni ìyìn yẹ. w20.07 15 ¶5-6
Thursday, October 27
Ohun tí Baba pa láṣẹ fún mi pé kí n ṣe gẹ́lẹ́ ni mò ń ṣe.—Jòh. 14:31.
Kì í ṣe torí pé Jésù ò gbọ́n tàbí pé kò mọ ohun tó yẹ kó ṣe ló ṣe ń fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà. Kódà, bí Jésù ṣe kọ́ni lọ́nà tó ṣe kedere fi hàn pé òun ló gbọ́n jù nínú gbogbo àwọn tó tíì gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Jòh. 7:45, 46) Jèhófà mọ̀ pé Jésù kúnjú ìwọ̀n ó sì máa ń ṣiṣẹ́ kára, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ kí Jésù ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òun nígbà tó ń dá gbogbo ohun tó wà lọ́run àti ayé. (Òwe 8:30; Héb. 1:2-4) Yàtọ̀ síyẹn, àtìgbà tí Jésù ti jíǹde ni Jèhófà ti fún un ní “gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé.” (Mát. 28:18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù gbọ́n gan-an, ó sì lágbára, ó ṣì fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ gan-an. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fi kókó yìí sọ́kàn o. Kì í ṣe torí pé Jèhófà ka àwọn ọkùnrin sí pàtàkì ju àwọn obìnrin lọ ló ṣe ní kí àwọn aya fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn. Ó ṣe tán, àtọkùnrin àtobìnrin ni Jèhófà yàn láti jọba pẹ̀lú Jésù. (Gál. 3:26-29) Jèhófà fi hàn pé òun fọkàn tán Jésù Ọmọ òun nígbà tó fún un ní ọlá àṣẹ. Lọ́nà kan náà, àwọn ọkọ tó gbọ́n máa ń fọkàn tán ìyàwó wọn, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí wọ́n bójú tó àwọn nǹkan kan nínú ilé. w21.02 11 ¶13-14
Friday, October 28
A ka àwọn tó ní ìfaradà sí aláyọ̀.—Jém. 5:11.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bíi dígí, ó ń jẹ́ ká rí àwọn ibi tá a kù sí àtàwọn ibi tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe. (Jém. 1:23-25) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a lè wá rí i pé ó yẹ ká túbọ̀ máa mú sùúrù, ká má sì tètè máa bínú. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa mú sùúrù tí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ tàbí tí àwọn èèyàn bá ṣe ohun tó lè mú wa bínú. Nípa bẹ́ẹ̀, àá lè fara balẹ̀ ronú, àá sì ṣèpinnu tó tọ́. (Jém. 3:13) Ẹ ò rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká lóye Bíbélì dáadáa! Nígbà míì, ẹ̀yìn tá a bá ṣàṣìṣe la máa ń kọ́gbọ́n. Àmọ́ ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà rí ọgbọ́n Ọlọ́run ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tó ṣe ohun tó dáa àtàwọn tó ṣàṣìṣe. Ìdí nìyẹn tí Jémíìsì fi gbà wá níyànjú pé ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kàn bí Ábúráhámù, Ráhábù, Jóòbù àti Èlíjà. (Jém. 2:21-26; 5:10, 11, 17, 18) Àwọn olóòótọ́ yìí kojú àwọn àdánwò tó le, síbẹ̀ wọn ò pàdánù ayọ̀ wọn. Bí wọ́n ṣe fara dà á jẹ́ ká rí i pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwa náà lè fara da ìṣòro, ká sì máa láyọ̀. w21.02 29-30 ¶12-13
Saturday, October 29
Ìmọ̀ràn máa ń jẹ́ kí ohun téèyàn fẹ́ ṣe yọrí sí rere, ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n sì ni kí o fi ja ogun rẹ.—Òwe 20:18.
Ojúṣe akéde tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ni láti ran akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ lọ́wọ́ kó lè lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ dáadáa. Tí akéde náà bá ní kó o tẹ̀ lé òun, fi sọ́kàn pé ṣe lẹ jọ ń ṣiṣẹ́ láti ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́. (Oníw. 4:9, 10) Ìbéèrè náà ni pé, kí làwọn nǹkan pàtó tó o lè ṣe nígbà tẹ́ ẹ bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà? Múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà sílẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ní kí akéde náà sọ díẹ̀ fún ẹ nípa akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Kí lo lè sọ fún mi nípa akẹ́kọ̀ọ́ náà? Ibo lẹ bá ìkẹ́kọ̀ọ́ yín dé? Àwọn nǹkan wo lẹ máa fẹ́ tẹnu mọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí? Ṣé ohunkóhun wà tí ẹ ò ní fẹ́ kí n sọ tàbí ṣe níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, àwọn nǹkan wo lẹ sì máa fẹ́ kí n ṣe tàbí sọ? Kí lẹ rò pé mo lè sọ táá fún akẹ́kọ̀ọ́ náà níṣìírí? Àmọ́ o, má retí pé akéde náà máa sọ ọ̀rọ̀ àṣírí akẹ́kọ̀ọ́ náà fún ẹ, ìwọ̀nba tó bá sọ fún ẹ máa jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kó o ṣe. Míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Joy sọ pé: “Irú ìjíròrò yìí máa ń jẹ́ káwọn tá a jọ ṣiṣẹ́ túbọ̀ mọ akẹ́kọ̀ọ́ náà, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n lè sọ ohun táá ṣe é láǹfààní.” w21.03 9 ¶5-6
Sunday, October 30
Tí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kó tó kórìíra yín.—Jòh. 15:18.
Lára ohun tó ń mú káwọn èèyàn kórìíra wa ni pé a máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Àwọn ìlànà yìí mú ká yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé tí wọ́n jẹ́ oníwàkiwà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ò rí ohun tó burú nínú ìṣekúṣe, irú èyí tí Ọlọ́run tìtorí ẹ̀ pa Sódómù àti Gòmórà run. (Júùdù 7) Torí pé a máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, a kì í sì í lọ́wọ́ sírú àwọn ìwàkiwà bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ pé a ò lajú. (1 Pét. 4:3, 4) Kí lá jẹ́ ká lè fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wa tí wọ́n sì ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́? A gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Ìgbàgbọ́ dà bí apata tó máa jẹ́ ká lè “paná gbogbo ọfà oníná ti ẹni burúkú náà.” (Éfé. 6:16) Yàtọ̀ sí ìgbàgbọ́, a tún nílò ìfẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìfẹ́ “kì í tètè bínú.” Ó máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra, ó sì máa ń fara da ìwà àìtọ́. (1 Kọ́r. 13:4-7, 13) Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn ará wa, títí kan àwọn ọ̀tá wa máa ń mú ká fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wa. w21.03 20-21 ¶3-4
Monday, October 31
Má ṣe máa yára bínú, torí pé àyà àwọn òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.—Oníw. 7:9.
Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, àwọn nǹkan kan wà tá ò ní máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ ká tètè máa bínú tí wọ́n bá sọ ohun tó dùn wá. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ ẹran ara òun kí wọ́n sì mu ẹ̀jẹ̀ òun tí wọ́n bá máa rí ìyè. (Jòh. 6:53-57) Ọ̀rọ̀ yẹn dẹ́rù ba ọ̀pọ̀ lára wọn, wọ́n sì fi í sílẹ̀. Àmọ́ àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ gidi ò fi í sílẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Jésù sọ yà wọ́n lẹ́nu, kò sì yé wọn, wọ́n dúró tì í gbágbáágbá. Wọn ò ronú pé ohun tí Jésù sọ ò tọ̀nà, kí wọ́n sì tìtorí ẹ̀ bínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fọkàn tán Jésù torí wọ́n mọ̀ pé òtítọ́ ló máa ń sọ. (Jòh. 6:60, 66-69) Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká má tètè máa bínú táwọn ọ̀rẹ́ wa bá sọ ohun tó lè múnú bí wa! Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká mú sùúrù kí wọ́n lè ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí.—Òwe 18:13. w21.01 11 ¶13