ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es22 ojú ìwé 108-118
  • November

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • November
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Tuesday, November 1
  • Wednesday, November 2
  • Thursday, November 3
  • Friday, November 4
  • Saturday, November 5
  • Sunday, November 6
  • Monday, November 7
  • Tuesday, November 8
  • Wednesday, November 9
  • Thursday, November 10
  • Friday, November 11
  • Saturday, November 12
  • Sunday, November 13
  • Monday, November 14
  • Tuesday, November 15
  • Wednesday, November 16
  • Thursday, November 17
  • Friday, November 18
  • Saturday, November 19
  • Sunday, November 20
  • Monday, November 21
  • Tuesday, November 22
  • Wednesday, November 23
  • Thursday, November 24
  • Friday, November 25
  • Saturday, November 26
  • Sunday, November 27
  • Monday, November 28
  • Tuesday, November 29
  • Wednesday, November 30
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
es22 ojú ìwé 108-118

November

Tuesday, November 1

Tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀rọ̀ láì tíì gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀, ìwà òmùgọ̀ ni, ó sì ń kó ìtìjú báni.​—Òwe 18:13.

Tí wọ́n bá ní ká sọ èrò wa nípa Jónà, torí pé ìwọ̀nba lohun tá a mọ̀ nípa ẹ̀, a lè sọ pé kì í ṣẹni tó ṣeé gbára lé, kò sì dúró ṣinṣin. Àbí kí ni ká ti gbọ́, Jèhófà dìídì rán Jónà pé kó lọ kéde ìdájọ́ òun fáwọn èèyàn Nínéfè, àmọ́ dípò kó gbabẹ̀ lọ, ṣe ló kọrí síbòmíì “kó lè sá fún Jèhófà.” (Jónà 1:1-3) Tó bá jẹ́ ìwọ ni, ṣé wàá tún gbéṣẹ́ yẹn fún un? Kò dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, Jèhófà rídìí tó fi yẹ kóun ṣe bẹ́ẹ̀. (Jónà 3:1, 2) Àdúrà tí Jónà gbà jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an. (Jónà 2:1, 2, 9) Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jónà gbàdúrà, ọ̀kan lára àdúrà tó gbà yìí jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe pé kò fẹ́ṣẹ́ ṣe. Àwọn ohun tó sọ nínú àdúrà yẹn fi hàn pé ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó moore, ó sì ṣe tán láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Abájọ tí Jèhófà fi gbójú fo àṣìṣe ẹ̀, tó gbọ́ àdúrà ẹ̀, tó sì jẹ́ kó máa báṣẹ́ wòlíì ẹ̀ lọ. Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí ẹ̀yin alàgbà máa “gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀” kẹ́ ẹ tó fúnni nímọ̀ràn! w20.04 15 ¶4-6

Wednesday, November 2

[Pọ́ọ̀lù] bá wọn fèròwérò látinú Ìwé Mímọ́, . . .  ó ń ṣàlàyé, ó sì ń tọ́ka sí àwọn ohun tó fi ẹ̀rí hàn.​—Ìṣe 17:​2, 3.

Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní gba àwọn ẹ̀kọ́ Kristi gbọ́, wọ́n sì gbára lé ẹ̀mí mímọ́ kí wọ́n lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n fara balẹ̀ ṣèwádìí kó lè dá wọn lójú pé inú Ìwé Mímọ́ làwọn ẹ̀kọ́ náà ti wá. (Ìṣe 17:11, 12; Héb. 5:14) Kì í ṣe bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn ló mú kí wọ́n gba àwọn ẹ̀kọ́ náà gbọ́, kì í sì í ṣe bí àwọn ará ṣe kó wọn mọ́ra nígbà tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ìjọ nìkan ló mú kí wọ́n sin Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ìmọ̀ tó péye” tí wọ́n ní nípa Jèhófà ló mú kí wọ́n nígbàgbọ́. (Kól. 1:9, 10) Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kì í yí pa dà. (Sm. 119:160) Bí àpẹẹrẹ, òtítọ́ yìí kò ní yí pa dà kódà tẹ́nì kan nínú ìjọ bá ṣe ohun tó dùn wá tàbí tó dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní yí pa dà tá a bá kojú àdánwò. Torí náà, a gbọ́dọ̀ mọ ẹ̀kọ́ Bíbélì dunjú ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé òtítọ́ ni. Bí ìdákọ̀ró kò ṣe ní jẹ́ kí ọkọ̀ ojú omi kan sojú dé lásìkò ìjì líle, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a kọ́ kò ṣe ní jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa sojú dé nígbà àdánwò. w20.07 9 ¶6-7

Thursday, November 3

Ó pàṣẹ fún wa pé ká wàásù fún àwọn èèyàn ká sì jẹ́rìí kúnnákúnná.​—Ìṣe 10:42.

Jésù gbà pé tá a bá ti àwọn arákùnrin òun tó jẹ́ ẹni àmì òróró lẹ́yìn, òun là ń tì lẹ́yìn. (Mát. 25:34-40) Ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù tá a lè gbà ti àwọn ẹni àmì òróró lẹ́yìn ni pé ká máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn bí Jésù ṣe pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Mát. 28:19, 20) Láìsí ìtìlẹyìn àwọn “àgùntàn mìíràn,” àwọn arákùnrin Kristi kò ní lè wàásù ìhìn rere náà dé gbogbo ayé. (Jòh. 10:16) Tó o bá wà lára àwọn àgùntàn mìíràn, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé bó o ṣe ń wàásù tó o sì ń sọni dọmọ ẹ̀yìn, àwọn ẹni àmì òróró nìkan kọ́ lò ń tì lẹ́yìn, ṣe lo tún ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jésù. A tún lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà àti Jésù tá a bá ń lo owó àtohun ìní wa fún ìtìlẹyìn iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń darí. (Lúùkù 16:9) Bí àpẹẹrẹ, a lè fi owó ti iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn. Lára ohun tí wọ́n ń lo owó yìí fún ni láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká máa fowó sínú àpótí láwọn ìpàdé wa, ká sì tún máa ṣèrànwọ́ fáwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ nínú ìjọ wa.​—Òwe 19:17. w20.04 24 ¶12-13

Friday, November 4

Kò ní ka Ọlọ́run àwọn bàbá rẹ̀ sí. . . . Àmọ́ dípò ìyẹn, ó máa yin ọlọ́run ibi ààbò lógo.​—Dán. 11:​37, 38.

Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe sọ, ọba àríwá kò “ka Ọlọ́run àwọn bàbá rẹ̀ sí.” Ọ̀nà wo ló gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ìjọba Soviet Union wá bó ṣe máa pa gbogbo ẹ̀sìn run, torí náà ó fojú àwọn ẹlẹ́sìn rí màbo, ó sì gba àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn. Kó lè mú ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ ṣẹ, lọ́dún 1918 ìjọba Soviet Union ṣòfin kan tó mú kí wọ́n máa kọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé pé kò sí Ọlọ́run. Báwo ni ọba àríwá ṣe “yin ọlọ́run ibi ààbò lógo”? Ìjọba Soviet Union ná òbítíbitì owó láti mú kí àwọn ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ lágbára gan-an àti láti ṣe àwọn ohun ìjà runlérùnnà kí ìjọba rẹ̀ lè túbọ̀ lágbára. Bó ṣe di pé tọ̀tún-tòsì wọn, ìyẹn ọba àríwá àti ọba gúúsù to àwọn ohun ìjà jọ pelemọ nìyẹn, kódà àwọn ohun ìjà náà lágbára débi pé wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ lè pa gbogbo ayé run! Ohun pàtàkì kan wà tí ọba àríwá ṣe ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ọba gúúsù, ohun náà ni pé wọ́n “gbé ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀.” Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni “ohun ìríra” náà.​—Dán. 11:31. w20.05 6-7 ¶16-17

Saturday, November 5

Arákùnrin rẹ . . . sọ nù, a sì rí i.​—Lúùkù 15:32.

Ta ló yẹ kó wá àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́? Iṣẹ́ gbogbo wa ni, yálà a jẹ́ alàgbà, aṣáájú-ọ̀nà, ẹbí tàbí ọ̀rẹ́, títí kan àwọn akéde. Ṣé o mọ ẹnì kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́? Ṣé o ti pàdé ẹnì kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tàbí níbi ìpàtẹ ìwé wa? Tẹ́ni náà bá fẹ́ kí àwọn alàgbà ran òun lọ́wọ́, gba àdírẹ́sì àti nọ́ńbà fóònù rẹ̀, kó o sì fún àwọn alàgbà ìjọ rẹ. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Thomas sọ pé: “Mo máa ń kọ́kọ́ wádìí lọ́wọ́ àwọn ará bóyá wọ́n mọ ibi tí àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ ń gbé. Mo sì lè bi wọ́n bóyá wọ́n mọ ẹnì kan tí kò wá sípàdé mọ́. Tí mo bá wá lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹni yẹn, mo máa ń béèrè nípa àwọn ọmọ wọn àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé, wọ́n máa ń mú àwọn ọmọ wọn dání. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ náà ti fìgbà kan rí jẹ́ akéde. Èyí sì máa ń béèrè pé ká ran àwọn náà lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ṣe dáadáa nínú ètò Ọlọ́run.” w20.06 24 ¶1; 25 ¶6-7

Sunday, November 6

Màá rántí àwọn iṣẹ́ Jáà; màá rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí o ti ṣe tipẹ́tipẹ́.​—Sm. 77:11.

Nínú gbogbo ohun tí Jèhófà dá sáyé, àwa èèyàn nìkan la lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ká sì fi ohun tá a kọ́ sílò. Èyí mú ká lè máa ṣàtúnṣe sí bá a ṣe ń ronú àti bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa. (1 Kọ́r. 6:9-11; Kól. 3:9, 10) Kódà, a lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Héb. 5:14) A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ká ṣojúure sí wọn, ká sì fàánú hàn sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, a lè fara wé bí Jèhófà ṣe máa ń ṣèdájọ́ òdodo. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà fi hàn pé a mọyì agbára tá a ní láti rántí nǹkan. Ọ̀kan ni pé ká má ṣe gbàgbé àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, bó ṣe ràn wá lọ́wọ́, tó sì tù wá nínú. Èyí máa jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú. (Sm. 77:12; 78:4, 7) Ohun míì tá a lè ṣe ni pé ká máa rántí ohun táwọn èèyàn ṣe fún wa, ká sì máa dúpẹ́ oore. Àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé àwọn tó bá moore máa ń láyọ̀. w20.05 23 ¶12-13

Monday, November 7

Bẹ̀rù orúkọ ológo, tó ń bani lẹ́rù yìí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní.​—Diu. 28:58.

Wo bó ṣe máa rí lára Mósè nígbà tó wà nínú ihò àpáta tó sì rí bí ògo Jèhófà ṣe ń kọjá. Ìwé Insight on the Scriptures sọ pé “ó jọ pé ìran tí Mósè rí yìí ló bani lẹ́rù jù nínú gbogbo ìran táwọn èèyàn rí kí Jésù Kristi tó wá sáyé.” Mósè wá gbọ́ ohùn kan nípasẹ̀ áńgẹ́lì tó sọ pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini.” (Ẹ́kís. 33:17-23; 34:5-7) Ó ṣeé ṣe kí Mósè máa rántí ìran náà nígbà tó dárúkọ Jèhófà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Nígbàkigbà táwa náà bá ń dárúkọ Jèhófà, ó yẹ ká máa ronú nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ó tún yẹ ká máa ronú nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀, ìyẹn bó ṣe jẹ́ alágbára, ọlọ́gbọ́n, onídàájọ́ òdodo àti Ọlọ́run ìfẹ́. Tá a bá ń ronú lórí àwọn ànímọ́ yìí àtàwọn ànímọ́ míì tó ní, àá túbọ̀ ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un.​—Sm. 77:11-15. w20.06 8-9 ¶3-4

Tuesday, November 8

Kí ìwọ má ṣe fi àwọn nǹkan tí o ti kọ́ sílẹ̀, tí a sì mú kí o gbà gbọ́.​—2 Tím. 3:14.

Jésù sọ pé ìfẹ́ la fi máa dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀. (Jòh. 13:34, 35) Àmọ́ ká tó lè nígbàgbọ́ tó lágbára tó sì dúró sán-ún, àwọn nǹkan míì wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Kì í ṣe ìfẹ́ tó wà láàárín ẹgbẹ́ ará nìkan ló yẹ kó mú ká máa jọ́sìn Jèhófà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká sọ pé ẹnì kan nínú ìjọ dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo, pàápàá tẹ́ni náà bá lọ jẹ́ alàgbà tàbí aṣáájú-ọ̀nà, kí lo rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí ìtara tó o ní? Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣe ohun tó dùn ẹ́ gan-an ńkọ́? Tàbí kẹ̀, kí ló lè ṣẹlẹ̀ tẹ́nì kan bá di apẹ̀yìndà, tó sì ń sọ pé irọ́ la fi ń kọ́ni? Tírú àwọn nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀, ṣé wàá ṣì máa sin Jèhófà, àbí wàá fi òtítọ́ sílẹ̀? Kókó ibẹ̀ rèé: Tó bá jẹ́ torí nǹkan táwọn míì ń ṣe nìkan ló mú kó o nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, ìgbàgbọ́ ẹ ò ní lágbára. Òótọ́ ni pé báwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn lè mú kó o nígbàgbọ́ déwọ̀n àyè kan. Àmọ́ ó tún yẹ kó o máa ka Bíbélì dáadáa, kó o lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́, kó o sì ṣèwádìí tó jinlẹ̀ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè dá ẹ lójú. Ó yẹ kó o fúnra rẹ ṣàwárí àwọn òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, kó o sì jẹ́ kó dá ẹ lójú.​—Róòmù 12:2. w20.07 8 ¶2-3

Wednesday, November 9

Ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tó jẹ́ aláìlera.​—Ìṣe 20:35.

Ọ̀pọ̀ ìrírí ló fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ń wá àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ tá a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (Ìfi. 14:6) Àpẹẹrẹ kan ni ti Silvio tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ecuador. Tọkàntọkàn ló fi gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ kóun lè pa dà sínú ìjọ. Àdúrà yẹn ló ń gbà lọ́wọ́ táwọn alàgbà méjì fi kan ilẹ̀kùn rẹ̀. Inú àwọn alàgbà náà dùn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n sì jẹ́ kó mọ àwọn nǹkan tó máa ṣe kó lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Inú wa máa dùn gan-an tá a bá ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Salvador fẹ́ràn kó máa ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́. Nígbà tó sọ bó ṣe máa ń rí lára ẹ̀, ó ní: “Lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe lomijé ayọ̀ máa ń dà lójú mi. Inú mi máa ń dùn pé mò ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́ láti já àwọn àgùntàn rẹ̀ gbà lọ́wọ́ Sátánì.” Tó o bá tiẹ̀ jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an. Ó fẹ́ kó o pa dà sọ́dọ̀ òun. Jèhófà ń dúró dè ẹ́ pé kó o pa dà sọ́dọ̀ òun. Tó o bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, tayọ̀tayọ̀ ló fi máa gbà ẹ́ pa dà. w20.06 29 ¶16-18

Thursday, November 10

O máa fi ojú ara rẹ rí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá.​—Àìsá. 30:20.

Torí pé Jèhófà ni ‘Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá,’ ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ká lè kẹ́kọ̀ọ́. (Àìsá. 30:21) À ń kẹ́kọ̀ọ́ bá a ṣe ń kà, tá a sì ń ṣàṣàrò nípa àwọn tó fìwà jọ Jèhófà. Bákan náà, à ń kẹ́kọ̀ọ́ bá a ṣe ń ronú nípa àwọn tí kò fìwà jọ Jèhófà tí wọn ò sì mọ̀wọ̀n ara wọn. (Sm. 37:37; 1 Kọ́r. 10:11) Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọba Sọ́ọ̀lù. Níbẹ̀rẹ̀, ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Kò gbéra ga, kódà ṣe ló sá pa mọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ fi jọba. (1 Sám. 9:21; 10:20-22) Àmọ́ nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù di agbéraga, ó sì jọ ara ẹ̀ lójú. Kò pẹ́ lẹ́yìn tó di ọba ló fi irú ẹni tó jẹ́ hàn. Nígbà kan, ó fi ìkánjú rú ẹbọ tó yẹ kí wòlíì Sámúẹ́lì rú. Ohun tó ṣe yẹn mú kó pàdánù ojúure Jèhófà, Jèhófà sì kọ̀ ọ́ ní ọba. (1 Sám. 13:8-14) Ìkìlọ̀ gidi lèyí jẹ́ fún wa pé ká má ṣe máa kọjá àyè ara wa. w20.08 10 ¶10-11

Friday, November 11

Ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tó ń . . . ṣe àbójútó yín nínú Olúwa.​—1 Tẹs. 5:12.

Òótọ́ ni pé Jèhófà ti tipasẹ̀ Jésù fún wa ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” nínú ìjọ Rẹ̀. (Éfé. 4:8) Lára “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” yìí ni àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí, àwọn olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí, àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, àwọn alábòójútó àyíká, àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run, àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ẹ̀mí mímọ́ ló yan gbogbo àwọn arákùnrin yìí kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ sìn wọ́n. (1 Pét. 5:2, 3) Ojúṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn arákùnrin tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yìí ní. Bí ọwọ́ àti ẹsẹ̀ àtàwọn ẹ̀yà ara míì ṣe máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú ara, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn arákùnrin tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kí gbogbo ìjọ lè jàǹfààní. Wọn kì í wá ògo fún ara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó jẹ wọ́n lógún ni bí wọ́n ṣe máa gbé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ró, kí ìjọ sì wà níṣọ̀kan. (1 Tẹs. 2:6-8) A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó fún wa láwọn arákùnrin tó ń fi ara wọn jìn fún wa yìí! w20.08 21 ¶5-6

Saturday, November 12

Ẹ lọ kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.​—Mát. 28:19.

Ọ̀kan lára ìdí tá a fi ń wàásù ni pé àwọn èèyàn dà bí àgùntàn “tí a bó láwọ, tí a sì fọ́n ká,” torí náà wọ́n nílò ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lójú méjèèjì. (Mát. 9:36) Bákan náà, Jèhófà fẹ́ kí onírúurú èèyàn ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́ kí wọ́n sì rí ìgbàlà. (1 Tím. 2:4) Tá a bá ń ronú nípa àǹfààní táwọn èèyàn máa rí nínú iṣẹ́ ìwàásù wa, á yá wa lára láti máa wàásù. Ńṣe là ń gba àwọn tá à ń wàásù fún là. (Róòmù 10:13-15; 1 Tím. 4:16) Àwa náà gbọ́dọ̀ ní irinṣẹ́ tá a máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Yàtọ̀ síyẹn, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn irinṣẹ́ náà lò dáadáa. Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni tó ṣe kedere. Ó sọ ohun tó yẹ kí wọ́n mú dání, ibi tí wọ́n ti máa wàásù àtohun tí wọ́n máa bá àwọn èèyàn sọ. (Mát. 10:5-7; Lúùkù 10:1-11) Lónìí, ètò Jèhófà ti pèsè Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ níbi tá a ti lè rí àwọn nǹkan tá a nílò láti ṣe iṣẹ́ náà yanjú. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ń kọ́ wa bá a ṣe lè lò wọ́n lọ́nà tó gbéṣẹ́. Bí wọ́n ṣe ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ yìí ń mú ká lè nígboyà ká sì túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.​—2 Tím. 2:15. w20.09 4 ¶6-7, 10

Sunday, November 13

Kò sí ohun tó ń mú inú mi dùn bíi kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.​—3 Jòh. 4.

Ẹ wo bínú àpọ́sítélì Jòhánù ṣe máa dùn tó nígbà tó gbọ́ pé àwọn tóun ràn lọ́wọ́ láti wá sínú òtítọ́ ṣì ń rìn nínú òtítọ́. Wọ́n kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro, Jòhánù sì ń sapá gan-an kó lè fún àwọn Kristẹni tó mú bí ọmọ yìí lókun. Lọ́nà kan náà, inú wa máa ń dùn nígbà táwọn ọmọ wa tàbí àwọn tá a mú bí ọmọ nínú ìjọ bá ya ara wọn sí mímọ́ sí Jèhófà tí wọ́n sì ń sìn ín nìṣó. (3 Jòh. 3) Ní nǹkan bíi 98 S.K., ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí Jòhánù kọ àwọn lẹ́tà mẹ́ta kan. Ó kọ àwọn lẹ́tà náà kó lè fún àwọn Kristẹni yẹn níṣìírí láti jẹ́ adúróṣinṣin kí wọ́n sì máa rìn nínú òtítọ́. Ọkàn Jòhánù ò balẹ̀ torí pé àwọn apẹ̀yìndà ti ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ èké nínú ìjọ. (1 Jòh. 2:18, 19, 26) Àwọn apẹ̀yìndà yẹn sọ pé àwọn mọ Ọlọ́run, àmọ́ wọn ò pa àwọn òfin Jèhófà mọ́. w20.07 20 ¶1-3

Monday, November 14

Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run; ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú èmi náà.​—Jòh. 14:1.

A gba ìhìn rere náà gbọ́, torí náà ó máa ń yá wa lára láti sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíì. Bákan náà, a gba àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì gbọ́. (Sm. 119:42; Àìsá. 40:8) Yàtọ̀ síyẹn, a ti rí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó nímùúṣẹ ní ọjọ́ wa. A ti rí ọ̀pọ̀ tó yí ìgbésí ayé wọn pa dà lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìlànà Bíbélì sílò. Àwọn nǹkan yìí mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé gbogbo èèyàn ló yẹ kó gbọ́ ìhìn rere náà. A tún nígbàgbọ́ nínú Jèhófà tó fún wa ní ìhìn rere náà àti Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba náà. Ohun yòówù ká kojú, Jèhófà máa jẹ́ ibi ààbò àti okun wa. (Sm. 46:1-3) Bákan náà, ó dá wa lójú pé Jésù ló ń darí iṣẹ́ yìí látọ̀run, ó sì ń lo agbára tí Jèhófà fún un. (Mát. 28:18-20) Ìgbàgbọ́ tá a ní ń mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún wa. w20.09 12 ¶15-17

Tuesday, November 15

Ohun tó dáa gan-an ló ṣe sí mi. . . . Ó ṣe ohun tó lè ṣe.​—Máàkù 14:​6, 8.

Nígbà míì, ó máa ń gba pé ká gbèjà àwọn arábìnrin wa tí wọ́n bá ń kojú ìṣòro. (Àìsá. 1:17) Bí àpẹẹrẹ, opó kan tàbí arábìnrin kan tóun àti ọkọ ẹ̀ ti fi ara wọn sílẹ̀ lè nílò ẹni tó máa ràn án lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn iṣẹ́ kan tí ọkọ ẹ̀ máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Arábìnrin àgbàlagbà kan lè nílò ẹni tó máa gbẹnu sọ fún un lọ́dọ̀ dókítà. Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń yọ̀ǹda ara ẹ̀ fáwọn iṣẹ́ kan nínú ètò Ọlọ́run lè nílò ẹni táá gbèjà ẹ̀ táwọn kan bá ń fẹ̀sùn kàn án pé kì í lọ sóde ẹ̀rí déédéé bíi tàwọn aṣáájú-ọ̀nà yòókù. Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ó máa ń yá Jésù lára láti gbèjà àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nígbà táwọn èèyàn bá ṣì wọ́n lóye. Bí àpẹẹrẹ, ó gbèjà Màríà nígbà tí Màtá fẹjọ́ ẹ̀ sùn. (Lúùkù 10:38-42) Ó tún gbèjà ẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì nígbà táwọn kan bẹnu àtẹ́ lù ú torí ohun tó ṣe. (Máàkù 14:3-9) Jésù mọ ìdí tí Màríà fi ṣe àwọn nǹkan tó ṣe, ó sì gbóríyìn fún un. Kódà, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn á máa rántí ohun tó ṣe yẹn ní “ibikíbi tí a bá ti ń wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo ayé.” w20.09 24 ¶15-16

Wednesday, November 16

Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tó wà níkàáwọ́ yín, kí ẹ máa ṣe alábòójútó, kì í ṣe tipátipá àmọ́ kó jẹ́ tinútinú níwájú Ọlọ́run.​—1 Pét. 5:2.

Olùṣọ́ àgùntàn tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ mọ̀ pé àgùntàn lè sọ nù. Tí àgùntàn kan bá sì ṣáko lọ, olùṣọ́ àgùntàn náà kò ní lù ú. Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jèhófà fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣe nígbà táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kan láyé àtijọ́ rẹ̀wẹ̀sì. Wòlíì Jónà ò lọ síbi tí Jèhófà rán an lọ. Síbẹ̀, Jèhófà ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sú òun. Torí pé olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni Jèhófà, ó dá Jónà nídè, ó sì fún un lókun tó mú kó lè ṣiṣẹ́ tó gbé fún un. (Jónà 2:7; 3:1, 2) Nígbà tó yá, Jèhófà lo ewéko akèrègbè kan láti kọ́ Jónà lẹ́kọ̀ọ́ kó lè mọ̀ pé ẹ̀mí èèyàn ṣe pàtàkì. (Jónà 4:10, 11) Kí la rí kọ́? Ẹ̀yin alàgbà ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn tó ṣáko lọ sú yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kẹ́ ẹ sapá láti lóye ohun tó mú kí wọ́n kúrò nínú agbo. Tí wọ́n bá sì ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ máa fìfẹ́ hàn sí wọn, kẹ́ ẹ sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ yín lógún. w20.06 20-21 ¶10-12

Thursday, November 17

A máa ràn wọ́n lọ́wọ́ díẹ̀.​—Dán. 11:34.

Lẹ́yìn tí ìjọba Soviet Union wá sópin tó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ lọ́dún 1991, àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà ní ilẹ̀ yẹn rí ‘ìrànlọ́wọ́ díẹ̀’ gbà ní ti pé wọ́n lómìnira. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti wàásù fàlàlà, ká tó ṣẹ́jú pẹ́ àwọn akéde tó wà lábẹ́ ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́ ti tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ di ọba àríwá. Ká tó lè sọ pé ẹnì kan ni ọba àríwá tàbí ọba gúúsù, ó gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta yìí: (1) ó máa ṣàkóso àwọn èèyàn Ọlọ́run tàbí kó ṣenúnibíni sí wọn, (2) ó máa ṣe ohun tó fi hàn pé ó kórìíra Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ àti (3) ó máa bá ọba kejì jà. Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà lábẹ́ àkóso wọn. Ohun tí wọ́n ń ṣe fi hàn pé wọ́n kórìíra Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. Bákan náà, wọ́n ń bá Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó jẹ́ ọba gúúsù jà. w20.05 12-13 ¶3-4

Friday, November 18

Máa kíyè sí . . . ẹ̀kọ́ rẹ nígbà gbogbo.​—1 Tím. 4:16.

Níwọ̀n bí a ò ti lè sọni dọmọ ẹ̀yìn tá ò bá mọ̀ọ̀yàn kọ́, ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè jẹ́ olùkọ́ tó já fáfá. Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn là ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé. Kò sí àní-àní pé a nífẹ̀ẹ́ ohun tá à ń kọ́ nínú Bíbélì. Torí náà, tá ò bá ṣọ́ra a lè sọ̀rọ̀ jù nípa wọn. Àmọ́, kò yẹ kí ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ máa sọ̀rọ̀ jù, yálà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ló ń darí tàbí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ tàbí nígbà tó bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tá a bá máa fi Bíbélì kọ́ni lóòótọ́, a ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ jù, kò sì yẹ ká ṣàlàyé gbogbo nǹkan tá a mọ̀ tán nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí kókó tá à ń jíròrò. (Jòh. 16:12) Bí àpẹẹrẹ, báwo ni ìmọ̀ tó o ní nígbà tó o ṣèrìbọmi ṣe pọ̀ tó tá a bá fi wé ohun tó o mọ̀ báyìí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ nìkan lo mọ̀ nígbà yẹn. (Héb. 6:1) Ọ̀pọ̀ ọdún ló gbà ẹ́ kó o tó mọ ohun tó o mọ̀ lónìí, torí náà má ṣe rọ́ gbogbo ẹ̀ sí akẹ́kọ̀ọ́ lórí lẹ́ẹ̀kan náà. w20.10 14-15 ¶2-4

Saturday, November 19

Ṣebí káfíńtà yẹn nìyí, ọmọ Màríà?​—Máàkù 6:3.

Àwọn òbí tó dáa jù ni Jèhófà yàn fún Jésù. (Mát. 1:18-23; Lúùkù 1:26-38) Àwọn ọ̀rọ̀ àtọkànwá tí Màríà sọ nínú Bíbélì jẹ́ ká rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an. (Lúùkù 1:46-55) Bákan náà, bí Jósẹ́fù ṣe ṣègbọràn sí ìtọ́ni Jèhófà fi hàn pé ó bẹ̀rù Jèhófà, ó sì fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú ẹ̀ dùn. (Mát. 1:24) Ẹ kíyè sí i pé kì í ṣe àwọn òbí tó lówó ni Jèhófà yàn pé kó bí Jésù. Àwọn ohun tí Jósẹ́fù àti Màríà fi rúbọ lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù fi hàn pé tálákà ni wọ́n. (Lúùkù 2:24) Kò sí àní-àní pé wọn ò gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ, torí nígbà tó yá, àwọn ọmọ wọn tó méje tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Mát. 13:55, 56) Àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà dáàbò bo ọmọ ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ pa á, àmọ́ kò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro. (Mát. 2:13-15) Bí àpẹẹrẹ, àwọn mọ̀lẹ́bí Jésù kan ò kọ́kọ́ gbà pé òun ni Mèsáyà. (Máàkù 3:21; Jòh. 7:5) Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí Jésù ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ nígbà tí Jósẹ́fù kú, ó sì dájú pé ìyẹn máa mú kí nǹkan nira fún un. w20.10 26-27 ¶4-6

Sunday, November 20

Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.​—Héb. 13:5.

Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹ́ rí bíi pé o dá wà tàbí pé o ò rẹ́ni ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó o níṣòro? Ó ti ṣe ọ̀pọ̀ bẹ́ẹ̀ rí títí kan àwọn tó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà. (1 Ọba 19:14) Tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ìwọ náà nìyẹn, rántí ìlérí tí Jèhófà ṣe pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.” Nípa bẹ́ẹ̀, àá lè fìgboyà sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù.” (Héb. 13:5, 6) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé tó kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni. Ohun tó sọ yìí rán wa létí ohun tó wà nínú Sáàmù 118:5-7. Bíi ti onísáàmù, àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù jẹ́ kóun náà gbà pé Jèhófà ni Olùrànlọ́wọ́ òun. Bí àpẹẹrẹ, lóhun tó lé lọ́dún méjì ṣáájú ìgbà tó kọ̀wé sáwọn Hébérù, díẹ̀ ló kù kí ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù bọ́ nígbà tó rìnrìn àjò tí ìjì líle kan sì bì lu ọkọ̀ ojú omi tó wà nínú ẹ̀. (Ìṣe 27:4, 15, 20) Jèhófà ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ nígbà ìrìn àjò yẹn àti nínú àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìrìn àjò náà. w20.11 12 ¶1-2

Monday, November 21

Má sọ pé, “Kí nìdí tí àwọn ọjọ́ àtijọ́ fi sàn ju ti ìgbà yìí lọ?”​—Oníw. 7:10.

Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu ká máa ronú pé nǹkan sàn fún wa tẹ́lẹ̀ ju ti ìsinsìnyí lọ? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ìgbà tí nǹkan dáa nìkan làá máa rántí. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì, àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ níbẹ̀ nígbà yẹn nìkan ni wọ́n rántí, wọn ò rántí baba ńlá ìyà tó jẹ wọ́n. Wọ́n sọ pé: “A ò jẹ́ gbàgbé ẹja tí a máa ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ nílẹ̀ Íjíbítì àti kùkúńbà, bàrà olómi, ewébẹ̀ líìkì, àlùbọ́sà àti ááyù!” (Nọ́ń. 11:5) Àmọ́, ṣé ọ̀fẹ́ ni oúnjẹ yẹn lóòótọ́? Rárá o. Ojú wọn rí màbo, kódà nígbà yẹn, ẹrú ni wọ́n ní Íjíbítì, wọ́n sì jẹ palaba ìyà. (Ẹ́kís. 1:13, 14; 3:6-9) Síbẹ̀, wọn ò rántí gbogbo ìyà tí wọ́n jẹ, àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ nìkan ni wọ́n rántí. Ìyẹn sì mú kí wọ́n gbàgbé àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe fún wọn. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn múnú bí Jèhófà gan-an.​—Nọ́ń. 11:10. w20.11 25 ¶5-6

Tuesday, November 22

Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá là.​—Sm. 34:​18, àlàyé ìsàlẹ̀.

Gbogbo wa ló máa ń wù pé ká pẹ́ láyé, kí ọkàn wa sì balẹ̀. Àmọ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ, ọjọ́ wa kúrú “wàhálà rẹ̀ sì máa ń pọ̀ gan-an.” (Jóòbù 14:1) Ìyẹn sì lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì nígbà míì. Irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan láyé àtijọ́. Kódà, wọ́n gbàdúrà pé káwọn kú. (1 Ọba 19:2-4; Jóòbù 3:1-3, 11; 7:15, 16) Ṣùgbọ́n léraléra ni Jèhófà Ọlọ́run wọn fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì fún wọn lókun. Ìrírí wọn wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ká lè rí ẹ̀kọ́ kọ́, kó sì tù wá nínú. (Róòmù 15:4) Ẹ ronú nípa àpẹẹrẹ Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù. Jósẹ́fù tó jẹ́ ààyò bàbá ẹ̀ wá di ẹrú lásán-làsàn nílé ọkùnrin kan tó jẹ́ abọ̀rìṣà nílẹ̀ Íjíbítì. (Jẹ́n. 37:3, 4, 21-28; 39:1) Ìyàwó Pọ́tífárì parọ́ mọ́ ọn pé ó fẹ́ fipá bá òun lò pọ̀. Láìdúró gbẹ́jọ́, Pọ́tífárì ju Jósẹ́fù sẹ́wọ̀n, wọ́n sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é. (Jẹ́n. 39:14-20; Sm. 105:17, 18) Ó dájú pé ìyẹn máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Jósẹ́fù gan-an! w20.12 16-17 ¶1-4

Wednesday, November 23

Kí orúkọ rẹ di mímọ́.​—Mát. 6:9.

Ohun tí Jésù sọ pé ó yẹ kó gbawájú nínú àdúrà wa nìyí. Àmọ́ kí ni Jésù ní lọ́kàn? Láti sọ ohun kan di mímọ́ túmọ̀ sí pé kéèyàn ya ohun náà sọ́tọ̀, kó sì jẹ́ mímọ́ láìní àbàwọ́n kankan. Àwọn kan lè wá béèrè pé, ‘Ṣebí mímọ́ lorúkọ Jèhófà, kò sì lábàwọ́n?’ Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ ká lè dáhùn ìbéèrè yìí ní kíkún, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí orúkọ dúró fún. Wọ́n máa ń kọ orúkọ sílẹ̀ tàbí pè é jáde láti fi dá ẹnì kan mọ̀. Bó ti wù kó rí, orúkọ kọjá ọ̀rọ̀ téèyàn wulẹ̀ kọ sílẹ̀ tàbí pè jáde. Bíbélì sọ pé: “Orúkọ rere ló yẹ kéèyàn yàn dípò ọ̀pọ̀ ọrọ̀.” (Òwe 22:1; Oníw. 7:1) Kí nìdí tí orúkọ fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé táwọn èèyàn bá gbọ́ orúkọ ẹnì kan, irú ẹni tónítọ̀hún jẹ́ ló máa wá sí wọn lọ́kàn. Torí náà, kì í ṣe bí wọ́n ṣe kọ orúkọ kan sílẹ̀ tàbí bí wọ́n ṣe ń pè é ló ṣe pàtàkì jù bí kò ṣe irú ẹni tónítọ̀hún jẹ́ àtohun táwọn èèyàn ń rò nípa ẹ̀. Nígbàkigbà táwọn èèyàn bá sọ ohun tí kò jóòótọ́ nípa Jèhófà, ṣe ni wọ́n ń tàbùkù sí orúkọ rẹ̀. Tí wọ́n bá sì tàbùkù sórúkọ rẹ̀, ṣe ni wọ́n ń bà á lórúkọ jẹ́. w20.06 3 ¶5-7

Thursday, November 24

Ìdààmú ti bá mi gidigidi, torí náà, mò ń bi ọ́, Jèhófà, ìgbà wo ló máa dópin?​—Sm. 6:3.

Tá a bá ń gbé àwọn ìṣòro wa sọ́kàn jù, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ. Bí àpẹẹrẹ, a lè máa ṣàníyàn pé owó tó ń wọlé lè má tó gbọ́ bùkátà wa tàbí pé a lè ṣàìsàn tí ò ní jẹ́ ká lè lọ síbi iṣẹ́ tàbí kíṣẹ́ tiẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ wa. Bákan náà, ẹ̀rù tún lè máa bà wá pé a lè rú òfin Ọlọ́run tá a bá kojú ìdẹwò. Yàtọ̀ síyẹn, láìpẹ́ Sátánì máa mú kí àwọn ìjọba ayé gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà, ẹ̀rù sì lè máa bà wá pé a lè bọ́hùn lásìkò yẹn. Torí náà, a lè máa ronú pé, ‘Ṣé ó burú tí mo bá ń ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan yìí ni?’ A mọ̀ pé Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ yéé ṣàníyàn.” (Mát. 6:25) Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé a ò gbọ́dọ̀ ṣàníyàn rárá àti rárá? Ó dájú pé ohun tó ń sọ kọ́ nìyẹn! Ó ṣe tán, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan láyé àtijọ́ ṣàníyàn, Jèhófà ò sì tìtorí ẹ̀ bínú sí wọn. (1 Ọba 19:4) Ṣe ni Jésù ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. Kò fẹ́ ká máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tá a nílò débi tá ò fi ní ráyè ìjọsìn Jèhófà. w21.01 3 ¶4-5

Friday, November 25

Orí obìnrin ni ọkùnrin.​—1 Kọ́r. 11:3.

Àwọn ọkọ máa jíhìn fún Jèhófà àti Jésù nípa ọwọ́ tí wọ́n fi mú ìdílé wọn. (1 Pét. 3:7) Torí pé Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ láyé àti lọ́run, ó láṣẹ láti fún àwa ọmọ rẹ̀ ní òfin nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà kó sì rí i dájú pé a pa àwọn òfin náà mọ́. (Àìsá. 33:22) Torí pé Jésù ni orí ìjọ, òun náà láṣẹ láti ṣe òfin kó sì rí i pé a pa òfin náà mọ́. (Gál. 6:2; Kól. 1:18-20) Bíi ti Jèhófà àti Jésù, olórí ìdílé kan ní àṣẹ láti ṣèpinnu fún ìdílé rẹ̀. (Róòmù 7:2; Éfé. 6:4) Àmọ́, ó níbi tí àṣẹ ẹ̀ mọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló yẹ kó máa tẹ̀ lé tó bá fẹ́ ṣèpinnu. (Òwe 3:5, 6) Yàtọ̀ síyẹn, olórí ìdílé kan kò láṣẹ láti ṣòfin fún àwọn tí kò sí nínú ìdílé ẹ̀. (Róòmù 14:4) Bákan náà, tí àwọn ọmọkùnrin tàbí àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ bá ti dàgbà, tí wọ́n sì ti wà láyè ara wọn, kò láṣẹ lórí wọn mọ́.​—Mát. 19:5. w21.02 2-3 ¶3-5

Saturday, November 26

Pèsè fún àwọn [tìrẹ].​—1 Tím. 5:8.

Ọ̀nà pàtàkì tí olórí ìdílé kan lè gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ìdílé òun ni pé kó máa pèsè fún wọn nípa tara. Àmọ́ ó gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé, àjọṣe tí ìdílé ẹ̀ ní pẹ̀lú Jèhófà lohun tó ṣe pàtàkì jù, kì í ṣe àwọn ohun ìní tara. (Mát. 5:3) Bí Jésù ṣe ń kú lọ lórí òpó igi oró, ó rí i dájú pé òun ṣètò ẹni tó máa bójú tó Màríà nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ń jẹ ìrora tó le gan-an, ó ṣètò pé kí àpọ́sítélì Jòhánù máa tọ́jú Màríà. (Jòh. 19:26, 27) Arákùnrin kan tó jẹ́ olórí ìdílé lè ní ọ̀pọ̀ ojúṣe láti bójú tó. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ kára níbi iṣẹ́ kí ìwà ẹ̀ lè máa fògo fún Jèhófà. (Éfé. 6:5, 6; Títù 2:9, 10) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún lè láwọn ojúṣe míì nínú ìjọ, bíi kó máa ṣiṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, kó sì máa múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bákan náà, ó ṣe pàtàkì kó máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀ déédéé. Ó dájú pé ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀ máa mọyì bó ṣe ń sapá láti mú kí ìlera wọn dáa, kí wọ́n láyọ̀, kí wọ́n sì ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà.​—Éfé. 5:28, 29; 6:4. w21.01 12 ¶15, 17

Sunday, November 27

[Aya tó dáńgájíá] ń ṣọ́ ohun tó ń lọ nínú agbo ilé rẹ̀.​—Òwe 31:27.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tí aya tó dáńgájíá máa ń ṣe, ó sọ pé ó lè bójú tó ilé, ó lè ra ilẹ̀ kó sì tà á, ó sì lè ṣòwò táá mérè wọlé. (Òwe 31:15, 16, 18) Kì í ṣe ẹrú tí ò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ nínú ilé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkọ ẹ̀ fọkàn tán an, ó sì máa ń tẹ́tí sí i. (Òwe 31:11, 26) Tí ọkọ kan bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún ìyàwó rẹ̀ láti fi ara ẹ̀ sábẹ́ rẹ̀. Láìka àwọn nǹkan tí Jésù gbé ṣe, kò ronú pé òun bu ara òun kù torí pé òun fara òun sábẹ́ Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:28; Fílí. 2:5, 6) Lọ́nà kan náà, aya tó dáńgájíá tó ń fara wé Jésù kò ní ronú pé òun ń bu ara òun kù tóun bá fi ara òun sábẹ́ ọkọ òun. Ìdí pàtàkì tó fi máa fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀ ni pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì mọyì àwọn ìlànà rẹ̀, kì í ṣe torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ọkọ ẹ̀ nìkan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé arábìnrin kan ń fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀, tí ọkọ ẹ̀ bá ní kó ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Bíbélì, kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. w21.02 11 ¶14-15; 12 ¶19

Monday, November 28

Ìpọ́njú ń mú ìfaradà wá.​—Róòmù 5:3.

Ọjọ́ pẹ́ táwa ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń fara da inúnibíni torí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn pàṣẹ fáwọn àpọ́sítélì pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, ìfẹ́ táwọn àpọ́sítélì náà ní fún Ọlọ́run mú kí wọ́n “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.” (Ìṣe 5:29; 1 Jòh. 5:3) Lónìí, irú ìfẹ́ yìí kan náà ló ń mú káwọn ará wa máa fara da inúnibíni àti ìwà ìkà táwọn aláṣẹ ń hù sí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kórìíra wa, a ò rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀, a kà á sí àǹfààní ńlá láti fara dà á. (Ìṣe 5:41; Róòmù 5:4, 5) Ó máa ń dunni gan-an tó bá jẹ́ pé àwọn tó wà nínú ìdílé wa ló ń ta kò wá. Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó ṣeé ṣe káwọn kan nínú ìdílé wa ronú pé wọ́n ti ṣì wá lọ́nà, àwọn míì sì lè ronú pé a ò mọ ohun tá à ń ṣe. (Fi wé Máàkù 3:21.) Wọ́n lè sọ̀rọ̀ burúkú sí wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ lù wá nígbà míì. Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu tí wọ́n bá ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí wa. Jésù sọ pé: “Àwọn ará ilé ẹni ló máa jẹ́ ọ̀tá ẹni.”​—Mát. 10:36. w21.03 21 ¶6-7

Tuesday, November 29

Ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára láti gbọ́rọ̀, kí wọ́n lọ́ra láti sọ̀rọ̀.​—Jém. 1:19.

Tó o bá tẹ̀ lé akéde kan lọ sọ́dọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀, tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ń sọ̀rọ̀. Ìyẹn lá jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kó o sọ àti ìgbà tó yẹ kó o sọ̀rọ̀. Àmọ́ o, á dáa kó o ronú jinlẹ̀ kó o tó sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, kò ní dáa kó o sọ̀rọ̀ jù tàbí kó o já ọ̀rọ̀ gbà mọ́ akéde náà lẹ́nu, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní dáa kó o gbé ọ̀rọ̀ gba ibòmíì. Lọ́wọ́ kejì, o lè ṣe àlàyé ṣókí tàbí àpèjúwe, o sì lè béèrè ìbéèrè táá mú kí ohun tí wọ́n ń jíròrò túbọ̀ ṣe kedere. Nígbà míì, o lè má ní ohun tó o máa fi kún àlàyé tí akéde náà ṣe. Àmọ́, o lè gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́ náà, kó o sì fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó lè tẹ̀ síwájú. Tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, o lè ṣàlàyé bó o ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, o lè sọ bó o ṣe borí ìṣòro kan tàbí bó o ṣe rọ́wọ́ Jèhófà láyé rẹ. (Sm. 78:4, 7) Ohun tó o sọ lè ṣe akẹ́kọ̀ọ́ náà láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára tàbí kó jẹ́ ohun tó nílò nìyẹn kó lè pinnu pé òun máa ṣèrìbọmi. w21.03 10 ¶9-10

Wednesday, November 30

Ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.​—Mát. 28:19.

Ta ló ń mú ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn? Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè yìí nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ní Kọ́ríńtì, ó ní: “Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, àmọ́ Ọlọ́run ló mú kó máa dàgbà, tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ẹni tó ń gbìn ló ṣe pàtàkì tàbí ẹni tó ń bomi rin, bí kò ṣe Ọlọ́run tó ń mú kó dàgbà.” (1 Kọ́r. 3:6, 7) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, Jèhófà ló yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ká sì máa fìyìn fún tá a bá ṣe àṣeyọrí èyíkéyìí lẹ́nu iṣẹ́ náà. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti bá Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ṣiṣẹ́? (2 Kọ́r. 6:1) A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń lo gbogbo àǹfààní tá a ní láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Jèhófà. A máa ń bomi rin irúgbìn òtítọ́ tá a gbìn sọ́kàn àwọn èèyàn, kì í ṣe pé ká kàn bá wọn sọ̀rọ̀ nìkan. Tẹ́nì kan bá tẹ́tí sọ́rọ̀ wa, a máa ń pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹ̀ ká lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú, inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń rí i tí Jèhófà ń ran ẹni náà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nígbèésí ayé ẹ̀. w20.05 30 ¶14, 16-18

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́