ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es22 ojú ìwé 118-128
  • December

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • December
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Thursday, December 1
  • Friday, December 2
  • Saturday, December 3
  • Sunday, December 4
  • Monday, December 5
  • Tuesday, December 6
  • Wednesday, December 7
  • Thursday, December 8
  • Friday, December 9
  • Saturday, December 10
  • Sunday, December 11
  • Monday, December 12
  • Tuesday, December 13
  • Wednesday, December 14
  • Thursday, December 15
  • Friday, December 16
  • Saturday, December 17
  • Sunday, December 18
  • Monday, December 19
  • Tuesday, December 20
  • Wednesday, December 21
  • Thursday, December 22
  • Friday, December 23
  • Saturday, December 24
  • Sunday, December 25
  • Monday, December 26
  • Tuesday, December 27
  • Wednesday, December 28
  • Thursday, December 29
  • Friday, December 30
  • Saturday, December 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2022
es22 ojú ìwé 118-128

December

Thursday, December 1

Ẹni tó ń ṣiyèméjì dà bí ìgbì òkun tí atẹ́gùn ń fẹ́ káàkiri.​—Jém. 1:6.

Nígbà míì, a lè má lóye àwọn nǹkan kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Ó sì lè jẹ́ pé Jèhófà ò dáhùn àdúrà wa lọ́nà tá a fẹ́. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú ká máa ṣiyèméjì. Tá ò bá ṣe ohunkóhun láti borí iyèméjì wa, ìgbàgbọ́ wa lè bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn, ká má sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà mọ́. (Jém. 1:7, 8) Èyí tó wá burú jù ni pé a lè pàdánù ìrètí ọjọ́ iwájú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìrètí wa wé ìdákọ̀ró. (Héb. 6:19) Ìdákọ̀ró ni kì í jẹ́ kí ọkọ̀ rì tàbí kọ lu àpáta tí ìjì bá ń jà. Àmọ́ kí ìdákọ̀ró kan tó lè ṣiṣẹ́ dáadáa, ṣéènì tí wọ́n fi so ó mọ́ ọkọ̀ náà kò gbọ́dọ̀ já. Tí ṣéènì náà bá dógùn-ún, ìdákọ̀ró náà ò ní wúlò mọ́. Bákan náà, tá a bá ń ṣiyèméjì, ìgbàgbọ́ wa ò ní lágbára mọ́. Tẹ́ni tó ń ṣiyèméjì bá kojú ìṣòro, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé bóyá làwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ. Téèyàn ò bá ti nígbàgbọ́ mọ́, kò lè nírètí. Ó dájú pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò lè láyọ̀ láé! w21.02 30 ¶14-15

Friday, December 2

Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.​—Jém. 2:23.

Ó ṣeé ṣe kí Ábúráhámù ti lé lẹ́ni àádọ́rin (70) ọdún nígbà tí òun àti ìdílé rẹ̀ fi ìlú Úrì sílẹ̀. (Jẹ́n. 11:31–12:4) Fún nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún ló sì fi ń ṣí kiri nínú àgọ́ nílẹ̀ Kénáánì. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ábúráhámù kú nígbà tó pé ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́sàn-án (175). (Jẹ́n. 25:7) Síbẹ̀, kò rí ìmúṣẹ ìlérí tí Jèhófà ṣe pé àwọn àtọmọdọ́mọ òun máa jogún ilẹ̀ Kénáánì. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣojú ẹ̀ nígbà tí Jèhófà fìdí Ìjọba tó ṣèlérí múlẹ̀. Bó ti wù kó rí, Bíbélì sọ pé Ábúráhámù “darúgbó, ayé rẹ̀ sì dára” kó tó kú. (Jẹ́n. 25:8) Láìka àwọn ìṣòro tí Ábúráhámù kojú sí, ó nígbàgbọ́ tó lágbára, ó sì fi sùúrù dúró de Jèhófà. Kí ló mú kó lè fara dà á? Ìdí ni pé jálẹ̀ ìgbésí ayé Ábúráhámù, Jèhófà dáàbò bò ó, ó sì mú un lọ́rẹ̀ẹ́. (Jẹ́n. 15:1; Àìsá. 41:8; Jém. 2:22) Bíi ti Ábúráhámù, àwa náà ń retí ìlú tó ní ìpìlẹ̀ tòótọ́. (Héb. 11:10) Àmọ́, a ò retí pé kí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ torí pé Jèhófà ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ lọ́dún 1914, ó sì ti ń ṣàkóso lọ́run. (Ìfi. 12:7-10) Ohun tó kù ni pé kí Ìjọba náà nasẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀ dórí ilẹ̀ ayé. w20.08 4-5 ¶11-12

Saturday, December 3

Èrò ọkàn èèyàn dà bí omi jíjìn, àmọ́ olóye ló ń fà á jáde.​—Òwe 20:5.

Ká tó lè fara balẹ̀ tẹ́tí sẹ́nì kan, ó ṣe pàtàkì pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká sì ní sùúrù. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí mẹ́ta ó kéré tán tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, kò ní jẹ́ ká máa ní èrò òdì nípa àwọn míì. Ìkejì, á jẹ́ ká lóye bí nǹkan ṣe rí lára àwọn arákùnrin wa, ìyẹn á sì mú ká túbọ̀ gba tiwọn rò. Ìkẹta, á jẹ́ ká lè ran ẹni náà lọ́wọ́ láti mọ àwọn nǹkan kan nípa ara ẹ̀. Àwọn ìgbà míì máa ń wà téèyàn kì í lè sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ àfìgbà tó bá rẹ́ni sọ ọ́ fún. Ó máa ń ṣòro fáwọn ará wa kan láti sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn torí ohun tójú wọn ti rí sẹ́yìn, àṣà ìbílẹ̀ wọn tàbí irú ẹni tí wọ́n jẹ́. Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wọn láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, àmọ́ tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá lóye bí nǹkan ṣe rí lára wọn gan-an. Tá a bá ń mú sùúrù fún wọn bíi ti Jèhófà, wọ́n á fọkàn tán wa. Tí wọ́n bá sì ṣe tán láti sọ ohun tó ń ṣe wọ́n fún wa, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn. w20.04 15-16 ¶6-7

Sunday, December 4

[Ẹ] máa mú àwọn èèyàn láàyè.​—Lúùkù 5:10.

Àwọn ẹja sábà máa ń wà níbi tí omi ti bá wọn lára mu tí oúnjẹ sì ti pọ̀. Ṣé àsìkò tó bá ti wu apẹja kan ló lè lọ pẹja? Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí arákùnrin kan tó ń gbé ní ọ̀kan lára àwọn erékùṣù Pàsífíìkì sọ nígbà tó pe míṣọ́nnárì kan pé káwọn jọ lọ pẹja. Míṣọ́nnárì náà sọ pé, “Màá wá bá ẹ láago mẹ́sàn-án àárọ̀ ọ̀la.” Arákùnrin náà dá a lóhùn pé, “Kò yé ẹ, kì í ṣe ìgbà tó bá wù wá la lè lọ pẹja, àsìkò tá a máa rẹ́ja pa la gbọ́dọ̀ lọ.” Lọ́nà kan náà, àwọn apẹja èèyàn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa ń lọ síbi tí wọ́n á ti rí àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń lọ lásìkò tí wọ́n á rí wọn bá sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù wàásù ní tẹ́ńpìlì, nínú sínágọ́gù, láti ilé dé ilé àti láwọn ọjà. (Ìṣe 5:42; 17:17; 18:4) Àwa náà gbọ́dọ̀ mọ bí nǹkan ṣe rí fáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Ó yẹ ká ṣe tán láti lọ wàásù níbi tá a ti lè rí àwọn èèyàn, ká sì mọ ìgbà tá a lè rí wọn bá sọ̀rọ̀.​—1 Kọ́r. 9:19-23. w20.09 4 ¶8-9

Monday, December 5

Nípa sísọ òótọ́, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú ká dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tó jẹ́ orí, ìyẹn Kristi.​—Éfé. 4:15.

Ọ̀nà kan tá a lè gbà di ọ̀rẹ́ Jésù ni pé ká máa ti ètò tí ìjọ bá ṣe lẹ́yìn. Àá túbọ̀ di ọ̀rẹ́ Jésù tó jẹ́ orí ìjọ tá a bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí Jésù sọ pé kó máa bójú tó wa. (Éfé. 4:16) Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run fẹ́ rí i dájú pé gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba là ń lò, a sì ń lò wọ́n lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ti da àwọn ìjọ mélòó kan pọ̀. Èyí ti mú ká túbọ̀ máa ṣọ́wó ná. Àmọ́, ìṣètò yìí ti mú kí àwọn akéde tọ́rọ̀ kàn ṣe àwọn àyípadà kan. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe káwọn akéde yìí ti mọwọ́ àwọn ará ìjọ tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n ti jọ wà. Àmọ́ ní báyìí, ètò Ọlọ́run ti ní kí wọ́n máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ míì. Ẹ wo bí inú Jésù ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí i táwọn akéde olóòótọ́ yìí ń mú ara wọn bá ipò tuntun náà mu! w20.04 24 ¶14

Tuesday, December 6

Ọba gúúsù máa fi ìwo kàn án.​—Dán. 11:40; àlàyé ìsàlẹ̀.

Ọba àríwá àti ọba gúúsù ṣì ń bára wọn jà kí wọ́n lè mọ ìjọba tó lágbára jù láyé. Bí àpẹẹrẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ìjọba Soviet Union àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso èyí tó pọ̀ jù lára ilẹ̀ Yúróòpù. Ohun tó ṣe náà mú kí ọba gúúsù dá ẹgbẹ́ apawọ́pọ̀jagun tó lágbára sílẹ̀, ìyẹn àjọ NATO. Ohun míì ni pé ọba àríwá àti ọba gúúsù ń ná òbítíbitì owó kí wọ́n lè kó ohun ìjà jọ kí wọ́n sì ní ẹgbẹ́ ológún tó lágbára jù lọ. Ọba àríwá bá ọ̀tá rẹ̀ yìí jà nínú àwọn ogun tí tọ̀tún tòsì wọn ti pọ̀n sẹ́yìn àwọn orílẹ̀-èdè ní Áfíríkà, Éṣíà àti Látìn Amẹ́ríkà. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ńṣe ni orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ túbọ̀ ń lo agbára wọn lọ́pọ̀ ibi láyé. Bákan náà, wọ́n ń fi àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé fimú fínlẹ̀ kí wọ́n lè jí ìsọfúnni ara wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọba yìí ń fi kọ̀ǹpútà gbéjà ko ara wọn kí wọ́n lè ba ètò ìṣòwò àti ìṣèlú ara wọn jẹ́. Láfikún sí èyí, Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé ọba àríwá ò ní ṣíwọ́ àtimáa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, ohun tó sì ń ṣe nìyẹn.​—Dán. 11:41. w20.05 13 ¶5-6

Wednesday, December 7

Èmi fúnra mi yóò wá àwọn àgùntàn mi, màá sì bójú tó wọn.​—Ìsík. 34:11.

“Ṣé obìnrin lè gbàgbé ọmọ rẹ̀ tó ṣì ń mu ọmú?” Ìbéèrè pàtàkì yìí ni Jèhófà béèrè nígbà ayé wòlíì Àìsáyà. Jèhófà wá sọ pé: “Tí àwọn obìnrin yìí bá tiẹ̀ gbàgbé, mi ò jẹ́ gbàgbé rẹ láé.” (Àìsá. 49:15) Jèhófà kì í sábà fi ara ẹ̀ wé abiyamọ, àmọ́ ó ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ẹsẹ yìí. Jèhófà lo ìfẹ́ tí abiyamọ kan máa ń ní sí ọmọ rẹ̀ láti ṣàpèjúwe ìfẹ́ tóun ní sáwọn ìránṣẹ́ òun. Ọ̀pọ̀ abiyamọ ló máa gbà pé òótọ́ ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Jasmin sọ, pé: “Téèyàn bá ń tọ́mọ lọ́wọ́, èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ ọmọ náà, ìfẹ́ yìí sì máa ń lágbára gan-an.” Jèhófà máa ń kíyè sí i tí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá pa ìpàdé tì, tí kò sì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù mọ́. Ẹ wá wo bó ṣe máa dùn ún tó bó ṣe ń rí i tí ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ ń di aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́dọọdún. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa yìí ló ti pa dà sínú ìjọ, kódà wọ́n ń ṣe dáadáa, inú wa sì ń dùn sí wọn! Ó wu Jèhófà pé kí gbogbo wọn pa dà sọ́dọ̀ òun, ohun táwa náà sì fẹ́ nìyẹn.​—1 Pét. 2:25. w20.06 18 ¶1-3

Thursday, December 8

Tẹ ojú [rẹ] mọ́ àwọn ohun tí a kò rí. . . . Nítorí àwọn ohun tí à ń rí wà fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ àwọn ohun tí a kò rí máa wà títí ayérayé.​—2 Kọ́r. 4:18.

Kì í ṣe gbogbo ìṣúra ló ṣeé fojú rí. Kódà, ọ̀pọ̀ ìṣúra tó ṣeyebíye jù lọ ni kò ṣeé fojú rí. Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tá a fi ṣúra sí ọ̀run, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé wọ́n ṣe pàtàkì ju ohun ìní èyíkéyìí lọ. Ó wá fi kún un pé: “Ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà.” (Mát. 6:19-21) Ká sòótọ́, téèyàn bá ka ohun kan sí pàtàkì, tọkàntọkàn ló fi máa wá a. Téèyàn bá sì ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà, ńṣe lonítọ̀hún ń “to ìṣúra pa mọ́ fún ara [rẹ̀] ní ọ̀run.” Jésù sọ pé irú ìṣúra bẹ́ẹ̀ ò lè bà jẹ́, olè ò sì lè jí i. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká “tẹ ojú wa mọ́ àwọn ohun tí a kò rí.” (2 Kọ́r. 4:17, 18) Lára ohun tí a kò rí yìí làwọn ìbùkún tá a máa gbádùn nínú ayé tuntun. Ṣé a máa ń fi hàn pé a mọyì àwọn ìṣúra náà? w20.05 26 ¶1-2

Friday, December 9

Ìtọ́ni mi máa rọ̀ bí òjò.​—Diu. 32:2.

Ṣe ni orin tí Mósè kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dà bí òjò winniwinni tó rọ̀ sórí koríko, ó mára tù wọ́n, ọkàn wọn sì balẹ̀. Báwo làwa náà ṣe lè kọ́ àwọn èèyàn lọ́nà táá mú kára tù wọ́n, kí ọkàn wọn sì balẹ̀? A lè fi orúkọ Jèhófà han àwọn èèyàn nínú Bíbélì wa nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé tàbí níbi térò pọ̀ sí. A lè fún wọn láwọn ìwé tó fani mọ́ra, àwọn fídíò tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, a sì lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa àwọn ìsọfúnni tó ń gbógo fún Jèhófà lórí ìkànnì wa. Yálà nílé ìwé, níbiiṣẹ́ tàbí tá a bá ń rìnrìn àjò, a lè lo gbogbo àǹfààní tó yọjú láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Baba wa ọ̀run, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tó jẹ́. A lè jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí Jèhófà máa ṣe fún aráyé àti bó ṣe máa sọ ayé yìí di Párádísè. Ó sì lè jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí wọ́n máa gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀, táá sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ṣe là ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Baba wa ọ̀run, èyí sì ń mú ká sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. Yàtọ̀ síyẹn, à ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé irọ́ làwọn onísìn fi ń kọ́ni nípa Jèhófà. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá à ń kọ́ wọn nìkan ló lè mú kí wọ́n ní ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀ kára sì tù wọ́n.​—Àìsá. 65:13, 14. w20.06 10 ¶8-9

Saturday, December 10

Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì pa dà sọ́dọ̀ yín.​—Mál. 3:7.

Àwọn ànímọ́ wo lá jẹ́ ká lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó fẹ́ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tá a lè rí kọ́ látinú àpèjúwe ọmọ kan tó filé sílẹ̀. (Lúùkù 15:17-24) Jésù ṣàlàyé nípa bí ọmọ náà ṣe pe orí ara rẹ̀ wálé tó sì pinnu pé òun máa pa dà sílé. Nígbà tí bàbá rẹ̀ rí i lọ́ọ̀ọ́kán, ó sáré lọ pàdé rẹ̀, ó gbá a mọ́ra, ó sì jẹ́ kó dá a lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ̀rí ọkàn ọmọ náà dà á láàmú, ó sì gbà pé òun ò yẹ lẹ́ni tí bàbá náà lè kà sí ọmọ. Bàbá yìí káàánú ọmọ tó ronú pìwà dà náà, ó sì ṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ kó mọ̀ pé òun ti yọ́nú sí i àti pé ọmọ ọ̀wọ́n ló jẹ́ sí òun. Bàbá náà wá ní kí wọ́n wọ aṣọ tó dáa sí i lọ́rùn, ó sì filé pọntí fọ̀nà rokà nítorí rẹ̀. Jèhófà ni bàbá inú àpèjúwe yẹn ń tọ́ka sí. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́, ó sì fẹ́ kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ òun. Bíi ti Jèhófà, ẹ jẹ́ káwa náà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sínú ìjọ. Àmọ́ èyí máa gba pé ká mú sùúrù fún wọn, ká gba tiwọn rò, ká sì nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. w20.06 25-26 ¶8-9

Sunday, December 11

Tí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín lóòótọ́, ẹ ó mọ òtítọ́, òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.​—Jòh. 8:​31, 32.

Jésù sọ pé àwọn kan máa fi “ayọ̀ tẹ́wọ́ gba” òtítọ́, àmọ́ wọ́n á pa dà sẹ́yìn nígbà tí wọ́n bá kojú àdánwò. (Mát. 13:3-6, 20, 21) Bóyá wọn ò mọ̀ pé àwọn máa kojú àdánwò táwọn bá di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Mát. 16:24) Wọ́n sì lè ronú pé téèyàn bá di Kristẹni, kò ní níṣòro kankan, ìgbé ayé ìdẹ̀rùn nìkan lá máa gbé. Àmọ́, ṣé èèyàn lè gbé inú ayé burúkú yìí kó má sì níṣòro? Rárá torí pé ipò nǹkan máa ń yí pa dà, èèyàn sì lè ní ẹ̀dùn ọkàn fúngbà díẹ̀ torí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀. (Sm. 6:6; Oníw. 9:11) Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ará wa ló ń fi hàn pé ó dá àwọn lójú pé inú òtítọ́ làwọn wà. Lọ́nà wo? Wọn kì í fi Jèhófà sílẹ̀ kódà tẹ́nì kan nínú ìjọ bá ṣe ohun tó dùn wọ́n tàbí tó dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo. (Sm. 119:165) Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá kojú àdánwò ni ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ ń lágbára. (Jém. 1:2-4) O gbọ́dọ̀ ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tìẹ náà lágbára bẹ́ẹ̀. w20.07 8 ¶1; 9 ¶4-5

Monday, December 12

Tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run.​—Jém. 1:5.

Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jàǹfààní látinú ohun tó o fẹ́ kà. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń ronú ohun tó o máa ṣe sí ìṣòro kan, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o rí àwọn ìlànà táá ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Fílí. 4:6, 7) Jèhófà fún wa ní ẹ̀bùn kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn ni pé a lè fojú inú wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ bá ò tiẹ̀ sí níbẹ̀. Kó o lè túbọ̀ lóye ìtàn Bíbélì kan, fojú inú wò ó pé o wà níbẹ̀ àti pé ìwọ gangan ni nǹkan náà ṣẹlẹ̀ sí. Ṣe bí ẹni pé ò ń rí ohun tí ẹni náà ń rí, o sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Ohun míì ni pé kó o máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ò ń kà. Ó ṣe pàtàkì kó o máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ò ń kà àti bó o ṣe lè fi ẹ̀kọ́ ibẹ̀ sílò. Ìyẹn á jẹ́ kó o rí bó ṣe tan mọ́ ohun tó o mọ̀ tẹ́lẹ̀, á sì jẹ́ kó o túbọ̀ lóye ohun tó ò ń kà. Tó o bá ń ka Bíbélì láìronú lórí ẹ̀, ṣe ló dà bí ẹni tó kó èlò ọbẹ̀ sórí tábìlì láìsè é. Tó o bá ń ronú jinlẹ̀, wàá túbọ̀ lóye ohun tó o kà. w21.03 15 ¶3-5

Tuesday, December 13

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, . . . mi ò sì yéé rántí rẹ nínú àwọn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi tọ̀sántòru.​—2 Tím. 1:3.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lè ronú pé ká sọ pé òun ò lo ara òun tó bẹ́ẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó ṣeé ṣe kóun má sí lẹ́wọ̀n. Ó ṣeé ṣe kó máa bínú sí àwọn ará tó wà ní Éṣíà torí wọ́n pa á tì, kó má sì fọkàn tán àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó kù mọ́. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà nígbà tí Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé wọ́n máa pa òun, ohun tó ṣe pàtàkì sí i jù ni bó ṣe máa fògo fún Jèhófà. Bákan náà, ó tún ń ronú nípa bó ṣe lè fún àwọn míì níṣìírí. Kò fi mọ síbẹ̀ o, ó tún máa ń gbàdúrà sí Jèhófà nígbà gbogbo. Dípò kó máa banú jẹ́ torí àwọn tó pa á tì, ṣe ló ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run torí àwọn ọ̀rẹ́ tó dúró tì í, tó sì ràn án lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù máa ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. (2 Tím. 3:16, 17; 4:13) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó dá a lójú pé Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ òun. w21.03 18 ¶17-18

Wednesday, December 14

Bí a ṣe kó àwọn èpò jọ, tí a sì dáná sun wọ́n, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rí ní ìparí ètò àwọn nǹkan.​—Mát. 13:40.

Láwọn ọdún mélòó kan lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn afàwọ̀rajà tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni rọ́ wọnú ìjọ, wọ́n sì ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni dípò ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Látìgbà yẹn títí di ọdún 1870, kò sí àwùjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó wà létòlétò tí wọ́n sì ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Àwọn èké Kristẹni ló gbòde kan bí ìgbà tí èpò bá gbalẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi ṣòro láti mọ àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́. (Mát. 13:36-43) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ kókó yìí? Èyí jẹ́ ká rí i pé ohun tí Bíbélì sọ nínú Dáníẹ́lì orí 11 nípa ọba àríwá àti ọba gúúsù kò kan àwọn alákòóso tàbí ìjọba tó wà nípò láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sí ọdún 1870. Kò sí àwùjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ tí wọ́n lè gbógun tì. Àmọ́, a lè retí pé kí ọba àríwá àti ọba gúúsù fara hàn lẹ́yìn ọdún 1870. w20.05 3 ¶5

Thursday, December 15

Orílẹ̀-èdè kan ti gòkè wá sí ilẹ̀ mi.​—Jóẹ́lì 1:6.

Wòlíì Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn eéṣú máa ya bo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n á jẹ ilẹ̀ náà run, gbogbo ohun tí wọ́n bá sì rí ni wọ́n á jẹ ní àjẹrun. (Jóẹ́lì 1:4) Àlàyé tá a ti máa ń ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni pé àwa èèyàn Jèhófà tá à ń fìtara wàásù, tá ò sì jẹ́ kí ohunkóhun dá wa dúró bíi tàwọn eéṣú yẹn ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ sí lára. A ṣàlàyé pé ìwàásù tá à ń ṣe ń fa ìparun fún “ilẹ̀” kan, ìyẹn àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ àkóso àwọn olórí ẹ̀sìn. Àmọ́ tá a bá ka àsọtẹ́lẹ̀ náà látòkèdélẹ̀, àá rí i pé ó yẹ ká tún òye wa ṣe. Kíyè sí ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa àwọn eéṣú tó bo ilẹ̀ náà, ó ní: “Màá lé àwọn ará àríwá [ìyẹn àwọn eéṣú náà] jìnnà sí yín.” (Jóẹ́lì 2:20) Tó bá jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń pa àṣẹ Jésù mọ́ pé kí wọ́n wàásù kí wọ́n sì sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn ni eéṣú náà ṣàpẹẹrẹ, kí nìdí tí Jèhófà fi ṣèlérí pé òun máa lé wọn jìnnà? (Ìsík. 33:7-9; Mát. 28:19, 20) Èyí fi hàn pé kì í ṣe àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà ni Jèhófà máa lé jìnnà bí kò ṣe ohun kan tàbí àwọn kan tó kórìíra àwọn èèyàn rẹ̀. w20.04 3 ¶3-5

Friday, December 16

Tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run.​—Jém. 1:5.

Kí ló yẹ ká ṣe tó bá ń ṣe wá bíi pé Jèhófà ò tètè dáhùn àdúrà wa? Jémíìsì sọ pé ká máa bẹ Ọlọ́run, ká má sì jẹ́ kó sú wa. Jèhófà ò ní bínú tá a bá ń bẹ̀ ẹ́ ṣáá pé kó fún wa ní ọgbọ́n, kò sì ní pẹ̀gàn wa. Ọ̀làwọ́ ni Jèhófà Baba wa ọ̀run, ó sì máa fún wa ní ọgbọ́n táá jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa. (Sm. 25:12, 13) Ó mọ ohun tá à ń kojú, ó máa ń dùn ún pé à ń jìyà, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé ìyẹn fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe ń fún wa lọ́gbọ́n? Jèhófà ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti fún wa ní ọgbọ́n. (Òwe 2:6) Ká tó lè ní ọgbọ́n yìí, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run déédéé. Àmọ́, kì í ṣe pé ká kàn rọ́ ìmọ̀ sórí o. Kí ọgbọ́n Ọlọ́run tó lè ṣe wá láǹfààní, a gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò nígbèésí ayé wa. Jémíìsì sọ pé: “Ẹ máa ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ, ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán.” (Jém. 1:22) Tá a bá ń fi ìmọ̀ràn Ọlọ́run sílò, àá lẹ́mìí àlàáfíà, àá máa fòye báni lò, àá sì máa ṣàánú. (Jém. 3:17) Èyí á jẹ́ ká lè fara da ìṣòro èyíkéyìí, a ò sì ní pàdánù ayọ̀ wa. w21.02 29 ¶10-11

Saturday, December 17

Ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan . . . ń mú kí ara máa dàgbà sí i.​—Éfé. 4:16.

Á túbọ̀ yá akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lára láti tẹ̀ síwájú kó sì ṣèrìbọmi táwọn míì nínú ìjọ bá ràn án lọ́wọ́. Gbogbo wa tá a wà nínú ìjọ là ń mú kí ìjọ túbọ̀ gbèrú. Aṣáájú-ọ̀nà kan sọ pé: “Wọ́n sábà máa ń sọ pé ẹnì kan ló ń bímọ, igba èèyàn ló ń wò ó. Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí tó bá kan ọ̀rọ̀ sísọni dọmọ ẹ̀yìn torí pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ lápapọ̀ ló máa ń ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti wá sínú òtítọ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe àwọn òbí ni láti tọ́ ọmọ wọn, tẹbítọ̀rẹ́, títí kan àwọn olùkọ́ ló máa ń ran ọmọ náà lọ́wọ́ kó lè yàn kó sì yanjú. Lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń gba ọmọ náà nímọ̀ràn, wọ́n sì máa ń kọ́ ọ láwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé. Lọ́nà kan náà, àwọn ará nínú ìjọ lè gba akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan níyànjú, kí wọ́n fún un níṣìírí, kí wọ́n sì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún un. Èyí á jẹ́ kó tẹ̀ síwájú títí táá fi ṣèrìbọmi. (Òwe 15:22) Kí nìdí tó fi yẹ kínú akéde tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ máa dùn táwọn míì nínú ìjọ bá ń ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́wọ́? Torí pé bí àwọn ará ṣe ń ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ á jẹ́ kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ̀. w21.03 8 ¶1-3

Sunday, December 18

Tí a bá sọ pé, “A ò ní ẹ̀ṣẹ̀,” à ń tan ara wa.​—1 Jòh. 1:8.

Gbogbo àwa Kristẹni lọ́mọdé àti lágbà ló yẹ ká ṣọ́ra kó má bàa di pé à ń lọ́wọ́ sóhun tínú Jèhófà ò dùn sí lẹ́sẹ̀ kan náà ká tún máa díbọ́n pé à ń sin Jèhófà. Àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́ kó ṣe kedere pé a ò lè máa hùwàkiwà ká sì sọ pé à ń rìn nínú òtítọ́. (1 Jòh. 1:6) Tá a bá fẹ́ kínú Jèhófà dùn sí wa nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú, a gbọ́dọ̀ máa rántí pé gbogbo ohun tá a bá ń ṣe ni Jèhófà ń rí. Lédè míì, kò sóhun tó ń jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀. (Héb. 4:13) Kò yẹ ká gba ohun táwọn èèyàn ayé ń sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀ gbọ́. Nígbà ayé Jòhánù, àwọn apẹ̀yìndà gbà pé èèyàn lè máa dẹ́ṣẹ̀ síbẹ̀ kó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Irú èrò yìí náà làwọn èèyàn ní lónìí. Ọ̀pọ̀ ló máa ń sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́ àmọ́ wọn ò fara mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa ẹ̀ṣẹ̀, ní pàtàkì tó bá kan ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń sọ pé ohun tó bá wu àwọn làwọn máa ṣe tó bá kan ìbálòpọ̀, wọ́n sì gbà pé ìgbésí ayé kan tó yàtọ̀ làwọn ń gbé, bẹ́ẹ̀ sì rèé ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo ni Jèhófà kà á sí. w20.07 22 ¶7-8

Monday, December 19

‘Ẹ ní ìfẹ́ ní ìṣe àti òtítọ́.’​—1 Jòh. 3:18.

Ṣé o máa ń gbèjà àwọn arábìnrin nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Àwọn ará kan kíyè sí i pé arábìnrin kan tí ọkọ ẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí máa ń pẹ́ dé sípàdé, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí ìpàdé bá sì ti parí ló máa ń lọ. Wọ́n tún kíyè sí i pé kì í sábà mú àwọn ọmọ ẹ̀ wá sípàdé. Torí náà, wọ́n ń sọ fún un ṣáá pé ó yẹ kí ọkọ ẹ̀ mọ̀ pé dandan ni kó máa mú àwọn ọmọ ẹ̀ wá sípàdé. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé gbogbo ohun tí arábìnrin náà lè ṣe ló ń ṣe. Ó mọ̀ pé abẹ́ ọkọ òun lòun wà, ó sì níbi tí àṣẹ òun mọ. Ṣe ló yẹ ká gbóríyìn fún arábìnrin náà, ká sì sọ àwọn nǹkan dáadáa tó ń ṣe fáwọn tó ń sọ̀rọ̀ yẹn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè pa wọ́n lẹ́nu mọ́. Àwọn alàgbà mọ̀ pé inú Jèhófà máa dùn táwọn bá ń bójú tó àwọn arábìnrin yẹn bó ṣe yẹ. (Jém. 1:27) Wọ́n máa ń fòye bá àwọn arábìnrin lò bíi ti Jésù, wọn kì í ṣòfin máṣu mátọ̀ níbi tó bá ti yẹ kí wọ́n gba tiwọn rò. (Mát. 15:22-28) Táwọn alàgbà bá ń sapá láti ran àwọn arábìnrin lọ́wọ́ lọ́nà tó ṣe pàtó, inú àwọn arábìnrin yẹn á dùn, wọ́n á sì gbà pé ètò Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn. w20.09 24-25 ¶17-19

Tuesday, December 20

[Ọlọ́run] ti jẹ́ kí Ọba Nebukadinésárì mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀.​—Dán. 2:28.

Ìgbà gbogbo ni wòlíì Dáníẹ́lì máa ń wojú Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà mú kó túmọ̀ àlá Nebukadinésárì, kò gbé ògo fún ara ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ló gbé ògo fún, tó fi hàn pé ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀. (Dán. 2:26-28) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ìtàn yìí? Táwọn ará bá ń gbádùn àsọyé wa tàbí tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ń méso rere jáde, Jèhófà ló yẹ ká gbógo fún. Ó yẹ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa pé Jèhófà ló jẹ́ kó ṣeé ṣe, kì í ṣe agbára wa. (Fílí. 4:13) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jésù là ń fara wé. Ó gbára lé Jèhófà. (Jòh. 5:19, 30) Jésù ò gbìyànjú ẹ̀ láé láti gbapò mọ́ Bàbá ẹ̀ lọ́wọ́. Fílípì 2:6 sọ fún wa pé Jésù “kò ronú rárá láti já nǹkan gbà, ìyẹn, pé kó bá Ọlọ́run dọ́gba.” Jésù fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà, ó mọ̀ pé ó níbi tí agbára òun mọ, torí náà ó bọ̀wọ̀ fún Bàbá ẹ̀. w20.08 11 ¶12-13

Wednesday, December 21

Ẹ sáré lọ́nà tí ẹ fi lè gbà á.​—1 Kọ́r. 9:24.

Àwọn kan lára àwọn tá a jọ ń sá eré ìje ìyè yìí nìkan ló mọ àwọn ìṣòro tí wọ́n ń bá yí, àwọn míì ò mọ̀ ọ́n torí pé ìṣòro náà kò hàn sójú táyé. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn èèyàn ò lóye àìsàn tó ń ṣe ẹ́, àpẹẹrẹ Méfíbóṣétì máa fún ẹ níṣìírí. (2 Sám. 4:4) Ó ní àìlera tó ń bá yí, yàtọ̀ síyẹn Ọba Dáfídì tún dá a lẹ́jọ́ láìgbọ́ tẹnu ẹ̀. Síbẹ̀, kò jẹ́ káwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i yẹn mú kó ṣinú rò, kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn nǹkan rere tó ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé ẹ̀ ló gbájú mọ́. Ó mọyì oore tí Dáfídì ti ṣe fún un sẹ́yìn. (2 Sám. 9:6-10) Torí náà, nígbà tí Dáfídì dá a lẹ́jọ́ láìgbọ́ tẹnu ẹ̀, Méfíbóṣétì fòye gbé ohun tó ṣẹlẹ̀. Kò jẹ́ kí àṣìṣe tí Dáfídì ṣe mú kí òun ṣinú rò. Kò sì dá Jèhófà lẹ́bi nítorí ohun tí Dáfídì ṣe. Ohun tó gbà á lọ́kàn ni bó ṣe máa ṣètìlẹyìn fún ọba tí Jèhófà yàn sípò. (2 Sám. 16:1-4; 19:24-30) Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ ìtàn Méfíbóṣétì sílẹ̀ sínú Ìwé Mímọ́ ká lè rí ẹ̀kọ́ kọ́.​—Róòmù 15:4. w20.04 26 ¶3; 30 ¶18-19

Thursday, December 22

Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá.​—1 Kọ́r. 3:9.

Àwọn kan nínú ìjọ lè jẹ́ míṣọ́nnárì, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àwọn ará yìí fi gbogbo ayé wọn ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba nǹkan tara làwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún yìí máa ń ní, Jèhófà ń bù kún wọn lọ́pọ̀ jaburata. (Máàkù 10:29, 30) A mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ọ̀wọ́n yìí, a sì dúpẹ́ pé wọ́n wà pẹ̀lú wa nínú ìjọ! Ṣé àwọn tó ń múpò iwájú àtàwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nìkan ló ní ojúṣe pàtàkì nínú ìjọ? Rárá! Ìdí ni pé gbogbo akéde tó ń wàásù ìhìn rere ló ṣe pàtàkì sí Jèhófà. (Róòmù 10:15; 1 Kọ́r. 3:6-8) Kódà, ọ̀kan lára iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù nínú ìjọ ni pé ká máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20; 1 Tím. 2:4) Torí náà, gbogbo akéde tó wà nínú ìjọ ló ń sa gbogbo ipá wọn lẹ́nu iṣẹ́ yìí, yálà wọ́n ti ṣèrìbọmi tàbí wọn ò tíì ṣe bẹ́ẹ̀.​—Mát. 24:14. w20.08 21 ¶7-8

Friday, December 23

Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.​—Mát. 28:20.

Bá a ṣe sọ nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní, tá a bá kojú ìṣòro, Jésù máa tì wá lẹ́yìn. Ọ̀rọ̀ Jésù yìí máa ń fún wa lókun. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn ọjọ́ kan máa ń wà tí nǹkan kì í dẹrùn. Bí àpẹẹrẹ, téèyàn wa bá kú, ọgbẹ́ ọkàn tá a máa ń ní kì í lọ láàárín ọjọ́ mélòó kan, nígbà míì, ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn míì ń fara da ìṣòro tó máa ń bá ọjọ́ ogbó rìn. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ làwọn míì sì fi máa ń ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn. Èyí ó wù kó jẹ́, àá lè fara dà á torí a mọ̀ pé Jésù wà pẹ̀lú wa ní “gbogbo ọjọ́” títí kan àwọn ọjọ́ tí nǹkan nira fún wa gan-an. (Mát. 11:28-30) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé Jèhófà máa ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́. (Héb. 1:7, 14) Bí àpẹẹrẹ, àwọn áńgẹ́lì ń tì wá lẹ́yìn, wọ́n sì ń tọ́ wá sọ́nà bá a ṣe ń wàásù “ìhìn rere Ìjọba yìí” fún “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n.”​—Mát. 24:13, 14; Ìfi. 14:6. w20.11 13-14 ¶6-7

Saturday, December 24

Èrò ọkàn èèyàn dà bí omi jíjìn, àmọ́ olóye ló ń fà á jáde.​—Òwe 20:5.

A fẹ́ kẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ pé inú Bíbélì lohun tá à ń kọ́ ọ ti wá. (1 Tẹs. 2:13) Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Sọ fún un pé kó ṣàlàyé àwọn nǹkan tó ń kọ́ fún ẹ. Dípò tí wàá fi máa ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún un ní gbogbo ìgbà, ní kó ṣàlàyé àwọn kan fún ẹ. Jẹ́ kó rí bó ṣe lè fi àwọn ohun tó ń kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ sílò ní ìgbésí ayé ẹ̀. Lo àwọn ìbéèrè tó ń tọ́ni sọ́nà àtàwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kó o mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kó o mọ èrò ẹ̀ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó kà. (Lúùkù 10:25-28) Bí àpẹẹrẹ, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Èwo nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ nípa ẹ̀?” “Báwo lo ṣe lè fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sílò?” “Báwo ni ohun tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà yìí ṣe rí lára ẹ?” Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ ohun tó ń kọ́, kó sì máa fi í sílò, kì í ṣe bí ìmọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó. Bíbélì ni kó o fi máa kọ́ni. O gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kó o tó lè sunwọ̀n sí i. w20.10 15 ¶5-6

Sunday, December 25

Fún irúgbìn rẹ ní àárọ̀, má sì dẹwọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.​—Oníw. 11:6.

Ó dájú pé a máa parí iṣẹ́ ìwàásù yìí lásìkò. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà. Jèhófà fi hàn pé Olùpàkókòmọ́ ni òun. Ọgọ́fà ọdún (120) ṣáájú Ìkún Omi ni Jèhófà ti pinnu ọjọ́ tí òun máa pa àwọn èèyàn burúkú náà run. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ áàkì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì (40) sí àádọ́ta (50) ọdún kí Ìkún Omi náà tó bẹ̀rẹ̀, Nóà ò dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un. Bí àwọn èèyàn ò tiẹ̀ tẹ́tí sí i, ó ń kìlọ̀ fún wọn títí dìgbà tí Jèhófà sọ fún un pé kó wọ inú ọkọ̀ náà. Nígbà tó sì tó àkókò, “Jèhófà ti ilẹ̀kùn pa.” (Jẹ́n. 6:3; 7:1, 2, 16) Láìpẹ́, Jèhófà máa fòpin sí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe yìí, á “ti ilẹ̀kùn pa” mọ́ ayé Sátánì, ayé tuntun á sì wọlé dé. Títí dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká fara wé Nóà àtàwọn míì tí kò dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wọn. Ẹ jẹ́ ká gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, ká máa mú sùúrù, ká sì nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà pé á mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. w20.09 13 ¶18-19

Monday, December 26

Ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó bójú mu àti létòlétò.​—1 Kọ́r. 14:40.

Tí ò bá sí àwọn tó ń múpò iwájú, nǹkan máa rí rúdurùdu, a ò sì ní láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, tí kò bá sí àwọn tó ń múpò iwájú, a ò ní mọ àwọn tó yẹ kó ṣe ìpinnu, a ò sì ní mọ àwọn tó yẹ kó ṣiṣẹ́ lórí ìpinnu náà. Tí ètò tí Jèhófà ṣe pé káwọn ọkùnrin jẹ́ olórí ìdílé bá ń ṣeni láǹfààní lóòótọ́, kí nìdí tó fi ń ṣe ọ̀pọ̀ obìnrin bíi pé àwọn ọkọ wọn ń jẹ gàba lé wọn lórí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ọkùnrin ni kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n bójú tó ìdílé wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ àṣà ìbílẹ̀ wọn ni wọ́n ń tẹ̀ lé. Wọ́n tún máa ń le koko mọ́ àwọn ìyàwó wọn láti fi hàn pé àwọn ni olórí ìdílé. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ kan lè máa jẹ gàba lórí ìyàwó ẹ̀ torí ó fẹ́ káwọn èèyàn gbà pé ọkùnrin lòun tàbí torí pé kò fẹ́ kí wọ́n máa fojú “gbẹ̀wù dání” wo òun. Ó lè ronú pé òun ò lè fipá mú ìyàwó òun láti nífẹ̀ẹ́ òun, àmọ́ òun lè mú kó máa bẹ̀rù òun, á sì tipa bẹ́ẹ̀ máa darí ẹ̀ bó ṣe wù ú. Ṣe ló yẹ kí àwọn ọkọ máa bọlá kí wọ́n sì máa buyì kún ìyàwó wọn. Àmọ́ tí ọkọ kan bá ń hùwà burúkú sí ìyàwó ẹ̀, ohun tó ń ṣe lòdì sí ìlànà Jèhófà.​—Éfé. 5:25, 28. w21.02 3 ¶6-7

Tuesday, December 27

Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.​—1 Pét. 5:7.

Tí ohun kan bá ń kó ẹ lọ́kàn sókè, gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jèhófà máa dáhùn àdúrà ẹ, á sì fún ẹ ní “àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye” èèyàn. (Fílí. 4:6, 7) Jèhófà máa jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tù wá nínú, kó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀. (Gál. 5:22) Gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ pátápátá ni kó o sọ fún Jèhófà tó o bá ń gbàdúrà. Sọ ohun tó o fẹ́ kó ṣe fún ẹ gan-an. Jẹ́ kó mọ ìṣòro tó o ní àti bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ. Tí ojútùú bá wà sí ìṣòro náà, sọ fún un pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n àti okun tó o nílò láti yanjú ẹ̀. Tí kò bá sí nǹkan tó o lè ṣe sí ìṣòro náà, bẹ Jèhófà pé kó fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, kó o má bàa gbọ́rọ̀ náà sọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Tó o bá sọ ohun tó o fẹ́ kí Jèhófà ṣe gan-an nínú àdúrà ẹ, ìyẹn á jẹ́ kó o rí ọ̀nà tí Jèhófà gbà dáhùn àdúrà náà. Àmọ́ tí Jèhófà ò bá dáhùn àdúrà ẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Ohun kan ni pé bí Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa sọ ohun tá a fẹ́ gan-an, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe fẹ́ ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo.​—Lúùkù 11:8-10. w21.01 3 ¶6-7

Wednesday, December 28

[Jésù] sọ fún wọn pé: “Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń wá àyè láti ṣe bẹ́ẹ̀, àfi àwọn tó ní ẹ̀bùn rẹ̀.”​—Mát. 19:11.

Lára àwọn tó wà nínú ìjọ làwọn tọkọtaya tí kò bímọ àtàwọn tó ti bímọ. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó náà wà níbẹ̀. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó? Ojú tí Jésù fi wò wọ́n ló yẹ káwa náà máa fi wò wọ́n. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, kò ṣègbéyàwó. Ó wà láìní aya ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi gbogbo ayé ẹ̀ ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un. Kò sígbà kankan tí Jésù kọ́ni pé ó di dandan kéèyàn ṣègbéyàwó tàbí kéèyàn má ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ó sọ pé àwọn Kristẹni kan lè pinnu pé àwọn ò ní láya tàbí lọ́kọ. (Mát. 19:12) Jésù bọ̀wọ̀ fún àwọn tí kò ṣègbéyàwó. Kò ronú pé wọn ò dáa tó àwọn tó ṣègbéyàwó tàbí pé wọn ò tẹ́gbẹ́. Bíi ti Jésù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà kò gbéyàwó nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù ò fìgbà kankan sọ pé àwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó torí ó gbà pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa ṣèpinnu fúnra ẹ̀. w20.08 28 ¶7-8

Thursday, December 29

Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.​—1 Jòh. 4:16.

Àpọ́sítélì Jòhánù pẹ́ láyé, ó sì ní ọ̀pọ̀ ìrírí. Ó kojú onírúurú ìṣòro tó lè mú kó fi Jèhófà sílẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin bí Jésù ṣe pa láṣẹ. Ìyẹn mú kó dá Jòhánù lójú pé Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ òun àti pé wọ́n máa fún òun lókun láti kojú ìṣòro èyíkéyìí. (Jòh. 14:15-17; 15:10) Láìka ohun tí Sátánì àti àwọn èèyàn burúkú ṣe fún un, Jòhánù ṣì ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará lọ́rọ̀ àti níṣe. Bíi ti Jòhánù, inú ayé tí Sátánì ẹni burúkú náà ń ṣàkóso là ń gbé. (1 Jòh. 3:1, 10) Sátánì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe ká má bàa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa mọ́, àmọ́ kò lè rí i ṣe àfi tá a bá fàyè gbà á. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, àá sì jẹ́ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú wa á dùn pé a wà nínú ìdílé Jèhófà, àá sì gbádùn ìgbésí ayé wa gan-an.​—1 Jòh. 4:7. w21.01 13 ¶18-19

Friday, December 30

Ọlọ́run . . . ń fúnni ní ìfaradà.​—Róòmù 15:5.

Nǹkan ò rọrùn rárá nínú ayé tí Sátánì ń ṣàkóso yìí. Kódà, ìṣòro náà máa ń wọni lọ́rùn nígbà míì. (2 Tím. 3:1) Àmọ́ kò yẹ ká bẹ̀rù tàbí ká máa ṣàníyàn torí pé Jèhófà mọ ohun tá à ń bá yí. Jèhófà ṣèlérí fún wa pé òun máa fi ọwọ́ ọ̀tún òun dì wá mú tá a bá ṣubú. (Àìsá. 41:10, 13) Ó dá wa lójú hán-ún pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́, á lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti fún wa lókun tá a nílò ká lè fara da ìṣòro èyíkéyìí ká sì borí wọn. Àwọn fídíò àtàwọn àtẹ́tísí tó dá lórí ìtàn Bíbélì àti ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” máa jẹ́ kí àwọn ìtàn Bíbélì túbọ̀ ṣe kedere sí ẹ. Kó o tó gbádùn èyíkéyìí lára àwọn ìtẹ̀jáde yìí, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o rí àwọn ẹ̀kọ́ tó o lè fi sílò. Fojú inú wò ó pé ìwọ gangan ni nǹkan náà ṣẹlẹ̀ sí. Ronú jinlẹ̀ lórí ohun táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe sí ìṣòro wọn àti bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ẹ̀. Lẹ́yìn náà, wo bó o ṣe lè fi àwọn ẹ̀kọ́ náà sílò nígbèésí ayé ẹ. Dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́. O sì lè fi hàn pé o mọyì ohun tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ tíwọ náà bá ń wá bó o ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́, kó o sì fún wọn níṣìírí. w21.03 19 ¶22-23

Saturday, December 31

Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.​—Sm. 127:3.

Tẹ́ ẹ bá ti ṣègbéyàwó tẹ́ ẹ sì fẹ́ bímọ, ó yẹ kẹ́ ẹ bi ara yín pé: ‘Ṣé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ṣé òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú wa débi tí àá fi lè bójú tó ọmọ tí Jèhófà máa fún wa?’ (Sm. 127:4) Tó o bá sì ti bímọ, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mò ń kọ́ àwọn ọmọ mi pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ kára?’ (Oníw. 3:12, 13) ‘Ṣé mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè dáàbò bo àwọn ọmọ mi lọ́wọ́ ewu àti èròkerò?’ (Òwe 22:3) Kò ṣeé ṣe láti gba àwọn ọmọ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro. Àmọ́ o lè fìfẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà láti máa fi ìlànà Ọlọ́run sílò tí wọ́n bá kojú ìṣòro, torí kò sí bí wọn ò ṣe ní níṣòro. (Òwe 2:1-6) Bí àpẹẹrẹ, bí mọ̀lẹ́bí yín kan bá fi òtítọ́ sílẹ̀, lo Bíbélì láti jẹ́ káwọn ọmọ rẹ mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. (Sm. 31:23) Tó bá sì jẹ́ pé ẹnì kan ló kú, ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa tu àwọn ọmọ rẹ nínú fún wọn, tó sì máa jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀.​—2 Kọ́r. 1:3, 4; 2 Tím. 3:16. w20.10 27 ¶7

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́