ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es23 ojú ìwé 7-17
  • January

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • January
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2023
  • Ìsọ̀rí
  • Sunday, January 1
  • Monday, January 2
  • Tuesday, January 3
  • Wednesday, January 4
  • Thursday, January 5
  • Friday, January 6
  • Saturday, January 7
  • Sunday, January 8
  • Monday, January 9
  • Tuesday, January 10
  • Wednesday, January 11
  • Thursday, January 12
  • Friday, January 13
  • Saturday, January 14
  • Sunday, January 15
  • Monday, January 16
  • Tuesday, January 17
  • Wednesday, January 18
  • Thursday, January 19
  • Friday, January 20
  • Saturday, January 21
  • Sunday, January 22
  • Monday, January 23
  • Tuesday, January 24
  • Wednesday, January 25
  • Thursday, January 26
  • Friday, January 27
  • Saturday, January 28
  • Sunday, January 29
  • Monday, January 30
  • Tuesday, January 31
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2023
es23 ojú ìwé 7-17

January

Sunday, January 1

Afọ́jú tó ń fini mọ̀nà ni wọ́n.​—Mát. 15:14.

Jésù dẹ́bi fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn torí pé wọ́n ń fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé alágàbàgebè làwọn Farisí torí pé bí wọ́n ṣe máa wẹ ọwọ́ wọn látòkèdélẹ̀ jẹ wọ́n lógún ju kí wọ́n tọ́jú àwọn òbí wọn lọ. (Mát. 15:1-11) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn, Jésù ò dẹ́kun àtimáa sọ òtítọ́. Jésù tún jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹ̀kọ́ èké làwọn Farisí fi ń kọ́ni. Jésù ò sọ pé gbogbo ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni ni inú Ọlọ́run dùn sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa gba ojú ọ̀nà gbòòrò tó lọ sí ìparun, àmọ́ díẹ̀ làwọn tó máa gba ojú ọ̀nà tóóró tó lọ sí ìyè. (Mát. 7:13, 14) Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn kan máa ṣe bíi pé wọ́n ń sin Ọlọ́run, àmọ́ tí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀ ní ti gidi. Ó wá kìlọ̀ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tó ń wá sọ́dọ̀ yín nínú àwọ̀ àgùntàn, àmọ́ tó jẹ́ pé ọ̀yánnú ìkookò ni wọ́n ní inú. Àwọn èso wọn lẹ máa fi dá wọn mọ̀.”​—Mát. 7:15-20. w21.05 9 ¶7-8

Monday, January 2

Kò kárí sọ mọ́.​—1 Sám. 1:18.

Ẹlikénà tó jẹ́ ọmọ Léfì lọkọ Hánà, ó sì nífẹ̀ẹ́ Hánà gan-an. Àmọ́ Ẹlikénà ní ìyàwó míì tó ń jẹ́ Pẹ̀nínà. Ẹlikénà nífẹ̀ẹ́ Hánà ju Pẹ̀nínà lọ, bó ti wù kó rí “Pẹ̀nínà bí àwọn ọmọ, ṣùgbọ́n Hánà kò bímọ.” Ìyẹn mú kí Pẹ̀nínà máa “pẹ̀gàn rẹ̀ ṣáá kó lè múnú bí i.” Ọ̀rọ̀ náà dun Hánà gan-an. Kódà, Bíbélì sọ pé “ńṣe ló máa ń sunkún, tí kò sì ní jẹun.” Síbẹ̀, kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé Hánà wá bó ṣe máa gbẹ̀san. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fún Jèhófà, ó sì gbà pé Jèhófà máa dá sọ́rọ̀ náà lásìkò tó yẹ. (1 Sám. 1:2, 6, 7, 10) Kí la lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Hánà? Tẹ́nì kan bá ń ṣe bíi pé òun sàn jù wá lọ tàbí tó ń fojú kéré wa, ṣe ni ká fọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ dípò ká máa bá onítọ̀hún díje. Torí náà, kò ní dáa ká gbẹ̀san tàbí ká fi ibi san ibi. (Róòmù 12:17-21) Kàkà bẹ́ẹ̀, á dáa ká wá àlàáfíà pẹ̀lú ẹni náà. Kódà tẹ́ni náà ò bá yíwà pa dà, ọkàn tiwa máa balẹ̀, ara á sì tù wá. w21.07 17 ¶13-14

Tuesday, January 3

Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún onírúurú ojúkòkòrò.​—Lúùkù 12:15.

Ojúkòkòrò mú kí Júdásì Ìsìkáríọ́tù dalẹ̀ Jésù. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, èèyàn dáadáa ni tẹ́lẹ̀. (Lúùkù 6:13, 16) Kò sí àní-àní pé Júdásì Ìsìkáríọ́tù kúnjú ìwọ̀n, ó sì ṣeé fọkàn tán torí òun ni Jésù ní kó máa bójú tó àpótí owó. Àmọ́ nígbà tó yá, Júdásì bẹ̀rẹ̀ sí í jalè láìka àwọn ìkìlọ̀ tí Jésù ti ṣe nípa ojúkòkòrò. (Máàkù 7:22, 23; Lúùkù 11:39) Kò pẹ́ sígbà tí wọ́n máa pa Jésù ni ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kó hàn gbangba sáwọn yòókù pé olójúkòkòrò ni Júdásì. Lọ́jọ́ tá à ń sọ yìí, Símónì adẹ́tẹ̀ ló gba Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ títí kan Màríà àti Màtá lálejò. Nígbà tí wọ́n ń jẹun lọ́wọ́, Màríà dìde, ó sì da òróró onílọ́fínńdà tí owó ẹ̀ wọ́n gan-an sórí Jésù. Inú bí Júdásì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù ronú pé àwọn ò bá ta òróró yẹn káwọn sì lo owó ẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́ ohun tó wà lọ́kàn Júdásì yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Bíbélì sọ pé “olè ni” àti pé ṣe ló ń wá bó ṣe máa jí owó inú àpótí náà.​—Jòh. 12:2-6; Mát. 26:6-16; Lúùkù 22:3-6. w21.06 18 ¶12-13

Wednesday, January 4

Èmi abòṣì èèyàn! Ta ló máa gbà mí?​—Róòmù 7:24.

Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe ti pọ̀ jù, ṣé ó sì máa ń nira fún ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o rẹ́ni fi jọ. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Pọ́ọ̀lù ń ṣàníyàn, kì í ṣe lórí ìjọ kan ṣoṣo o, àmọ́ “lórí gbogbo ìjọ.” (2 Kọ́r. 11:23-28) Ṣé àìsàn tó ń ṣe ẹ́ ló ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ? Ṣe lọ̀rọ̀ ẹ dà bíi ti Pọ́ọ̀lù tí ìnira bá nítorí ‘ẹ̀gún kan tó wà nínú ara ẹ̀,’ tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àìlera ara, tó sì tìtorí ẹ̀ gbàdúrà lọ́pọ̀ ìgbà pé kí Jèhófà bá òun mú un kúrò. (2 Kọ́r. 12:7-10) Ṣé àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó o ní ló ń mú kó o rẹ̀wẹ̀sì? Ó ṣe Pọ́ọ̀lù bẹ́ẹ̀ náà rí. Ìgbà kan wà tó pe ara ẹ̀ ní “abòṣì èèyàn” nítorí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ rẹ̀ tó ń bá fà á. (Róòmù 7:21-24) Láìka àwọn ìṣòro tí Pọ́ọ̀lù ní sí, kò dẹ́kun àtimáa sin Jèhófà. Kí ló jẹ́ kó lè fara dà á? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé òun láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan, ó nígbàgbọ́ tó lágbára nínú ìràpadà. w21.04 22 ¶7-8

Thursday, January 5

Ọmọ èèyàn wá kó lè fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.​—Máàkù 10:45.

Ẹni pípé ni Ádámù nígbà tí Ọlọ́run dá a, àmọ́ nígbà tó ṣẹ̀, ó pàdánù àǹfààní tó ní àtèyí táwọn ọmọ ẹ̀ máa ní láti wà láàyè títí láé. Ṣe ni Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, torí náà, kò ní àwíjàre. Kò sí àní-àní pé ikú tọ́ sí Ádámù fún nǹkan tó ṣe. Àmọ́, àwọn ọmọ rẹ̀ ńkọ́, wọn ò ṣáà sí níbẹ̀ nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀? (Róòmù 5:12, 14) Kí ni Jèhófà máa ṣe láti dá wọn nídè? Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn nǹkan tóun máa ṣe láti dá àwọn ọmọ Ádámù nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jẹ́n. 3:15) Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, a ní ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ ká mọyì ìràpadà. Ìràpadà yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé. Ìràpadà yìí ló máa jẹ́ kí Jésù fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú. (1 Jòh. 3:8) Bákan náà, ìràpadà ló máa jẹ́ kí ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún ayé yìí nímùúṣẹ. Láìpẹ́ gbogbo ayé máa di Párádísè. w21.04 14 ¶1; 19 ¶17

Friday, January 6

Kí a sì batisí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín.​—Ìṣe 2:38.

Èrò rẹpẹtẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù. Ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá, èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì ń sọ. Ohun àrà ọ̀tọ̀ kan ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Ṣàdédé làwọn Júù kan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè ìbílẹ̀ àwọn àlejò náà! Àmọ́, ọ̀rọ̀ táwọn Júù yẹn sọ fáwọn àlejò náà àtohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ tún yani lẹ́nu jùyẹn lọ. Lára ohun tí wọ́n sọ fún wọn ni pé tí wọ́n bá nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, wọ́n máa rí ìyè àìnípẹ̀kun. Ohun tí àwọn àlejò yẹn gbọ́ lọ́jọ́ yẹn wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an. Kódà, wọ́n béèrè pé: “Kí ni ká ṣe?” Pétérù wá sọ fún wọn pé ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ṣèrìbọmi. (Ìṣe 2:37, 38) Mánigbàgbé lohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn ló ṣèrìbọmi lọ́jọ́ yẹn, tí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn Jésù. Àtìgbà yẹn ni iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn tí Jésù pa láṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu, iṣẹ́ yẹn la sì ń ṣe títí dòní. w21.06 2 ¶1-2

Saturday, January 7

Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, àmọ́ Ọlọ́run ló mú kó máa dàgbà, tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ẹni tó ń gbìn ló ṣe pàtàkì tàbí ẹni tó ń bomi rin, bí kò ṣe Ọlọ́run tó ń mú kó dàgbà.​—1 Kọ́r. 3:6, 7.

Ó lè ṣòro láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Àwọn èèyàn lè má nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa ta kò wá. Kí ni ò ní jẹ́ kó sú wa tá a bá ń wàásù nírú agbègbè yìí? Ká rántí pé inú ayé tó kún fún ìṣòro là ń gbé, ipò àwọn èèyàn sì máa ń yí pa dà. Torí náà àwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa lónìí lè nífẹ̀ẹ́ sí i nígbà míì. (Mát. 5:3) Àwọn kan tí ò kì í gbàwé wa tẹ́lẹ̀ ti wá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Bákan náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni Ọ̀gá ìkórè náà. (Mát. 9:38) Ó fẹ́ ká máa fúnrúgbìn ká sì máa bomi rin ín, àmọ́ Òun ló ń mú kó dàgbà. Yàtọ̀ síyẹn, tá ò bá tiẹ̀ lẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí, ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀. Ìdí ni pé kì í ṣe iye àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ló máa mú kí Jèhófà bù kún wa, ìsapá wa ló máa ń wò! w21.07 6 ¶14

Sunday, January 8

Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.​—Sm. 127:3.

Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè bímọ, ó sì fẹ́ ká kọ́ àwọn ọmọ náà kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ òun, kí wọ́n sì sin òun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà dá àwọn áńgẹ́lì lọ́lá gan-an, wọ́n sì lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan, síbẹ̀ wọn ò láǹfààní láti bímọ. Torí náà, ó yẹ kẹ́yin òbí mọyì àǹfààní tẹ́ ẹ ní láti bímọ. Ojúṣe ńlá lẹ̀yin òbí ní láti tọ́ àwọn ọmọ yín dàgbà nínú “ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.” (Éfé. 6:4; Diu. 6:5-7) Kí àwọn òbí lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyanjú, ètò Ọlọ́run ti pèsè ìwé lóríṣiríṣi, fídíò, orin àtàwọn ìtẹ̀jáde orí ìkànnì. Kò sí àní-àní pé Baba wa ọ̀run àti Ọmọ rẹ̀ mọyì àwọn ọmọdé gan-an. (Lúùkù 18:15-17) Inú Jèhófà máa ń dùn táwọn òbí bá gbára lé e, tí wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti bójú tó àwọn ọmọ wọn. Ńṣe ni irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ mú kó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ wọn láti di ara ìdílé Jèhófà títí láé! w21.08 5 ¶9

Monday, January 9

Ìgbàgbọ́ ni . . . ẹ̀rí tó dájú nípa àwọn ohun gidi tí a kò rí.​—Héb. 11:1.

Àwọn kan ronú pé tẹ́nì kan bá sọ pé òun nígbàgbọ́, ṣe lẹni náà kàn gba ohun kan gbọ́ láìsí ẹ̀rí tó dájú. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé ìgbàgbọ́ jẹ́ kọ́ nìyẹn. A nígbàgbọ́ nínú àwọn ohun gidi tí a kò rí bíi Jèhófà, Jésù àti Ìjọba Ọlọ́run. Ìdí sì ni pé a ní ẹ̀rí tó ṣe kedere pé wọ́n wà. (Héb. 11:3) Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé: “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba ohun kan gbọ́ láìsí ẹ̀rí tó ṣe kedere, a kì í sì fọwọ́ rọ́ ìwádìí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sẹ́yìn.” Tí ẹ̀rí tó ṣe kedere bá wà pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan, ‘kí wá nìdí tí ọ̀pọ̀ ò fi gbà pé Ẹlẹ́dàá wà?’ Àwọn kan ò tiẹ̀ ṣèwádìí nípa ọ̀rọ̀ náà rí. Robert tó ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí sọ pé: “Ohun tí wọ́n kọ́ wa níléèwé ni pé kò sí Ẹlẹ́dàá, ìyẹn mú kí èmi náà gbà pé kò sẹ́ni tó dá wa. Kódà, mo ti lé lọ́mọ ogún (20) ọdún kó tó di pé mo rí ẹni tó fi Bíbélì ṣàlàyé fún mi lọ́nà tó ṣe kedere pé Ẹlẹ́dàá wà.” w21.08 15 ¶4-5

Tuesday, January 10

Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé ẹni rere ni Jèhófà.​—Sm. 34:8.

A lè túbọ̀ mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere tá a bá ń ka Bíbélì, tá a sì ń bi àwọn míì nípa bí Jèhófà ṣe bù kún wọn. Àmọ́, ó dìgbà tá a bá “tọ́” Jèhófà wò fúnra wa ká tó lè mọ bí oore ẹ̀ ṣe pọ̀ tó. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ó wù wá láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àmọ́ ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa gba pé ká ṣe àwọn àyípadà kan. A mọ ìlérí tí Jésù ṣe pé tá a bá fi ire Ìjọba náà sípò àkọ́kọ́, Jèhófà máa pèsè gbogbo ohun tá a nílò. Àmọ́ àwa fúnra wa ò tíì gbé ìgbésẹ̀ débi tá a fi máa rí bí Jèhófà ṣe ń mú ìlérí yẹn ṣẹ. (Mát. 6:33) Torí pé a nígbàgbọ́ nínú ìlérí tí Jésù ṣe, a dín ìnáwó wa kù, a dín iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa kù, a sì gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwa fúnra wa máa rí bí Jèhófà ṣe ń pèsè àwọn nǹkan tá a nílò. Nípa bẹ́ẹ̀, à ń “tọ́” Jèhófà wò, àá sì rí i pé ẹni rere ni. w21.08 26 ¶2

Wednesday, January 11

Wọn ò ní tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní.​—2 Tím. 4:3.

Ṣé irú ìṣòro yìí wà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Inú àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì máa ń dùn tí àwọn olówó, àwọn tó lẹ́nu láwùjọ àtàwọn tí ayé kà sí pàtàkì bá ń wá sí ṣọ́ọ̀ṣì wọn. Àwọn àlùfáà máa ń yọ̀ mọ́ àwọn èèyàn yìí bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwà wọn àti ìgbésí ayé wọn ò bá ìlànà Ọlọ́run mu. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn àlùfáà yìí kan náà máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá à ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì torí pé a ò lẹ́nu láwùjọ. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, àwa táwọn èèyàn ń “fojú àbùkù wò” ni Ọlọ́run yàn. (1 Kọ́r. 1:26-29) Báwọn èèyàn tiẹ̀ ń fojú àbùkù wò wá, gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà la ṣeyebíye lójú rẹ̀. Kí ni ò ní jẹ́ ká máa fojú táyé fi ń wò wá wo ara wa? (Mát. 11:25, 26) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwa èèyàn Jèhófà, má ṣe jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ. Fi sọ́kàn pé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́. (Sm. 138:6) Sì máa ronú nípa àwọn ohun ribiribi tí Jèhófà ti gbé ṣe nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ táwọn èèyàn ò kà sí ọlọ́gbọ́n tàbí amòye. w21.05 8 ¶1; 9 ¶5-6

Thursday, January 12

Ẹ fi nǹkan tí mo nílò ránṣẹ́ sí mi.​—Fílí. 4:16.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọyì ìrànlọ́wọ́ táwọn ará ṣe fún un. Ìrẹ̀lẹ̀ mú kó gbà káwọn míì ran òun lọ́wọ́. (Fílí. 2:19-22) Ẹ̀yin àgbàlagbà, onírúurú ọ̀nà lẹ lè gbà fi hàn pé ẹ mọyì àwọn ọ̀dọ́ tó wà níjọ yín. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá fẹ́ bá yín ṣe àwọn nǹkan kan, bóyá wọ́n fẹ́ fi ọkọ̀ gbé yín, wọ́n fẹ́ bá yín ra ọjà tàbí ṣe àwọn nǹkan míì, ẹ jẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, kẹ́ ẹ sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Fi sọ́kàn pé torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ ló ṣe ń lò wọ́n láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, ìyẹn sì lè mú kíwọ àtàwọn ọ̀dọ́ náà di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Bákan náà, máa sapá nígbà gbogbo láti ran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé inú ẹ máa ń dùn tó o bá rí àwọn ọ̀dọ́ tó ń sapá láti máa ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọ. Yàtọ̀ síyẹn, máa lo àkókò pẹ̀lú wọn, kó o sì sọ àwọn ìrírí tó o ti ní nígbèésí ayé fún wọn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé ò ń “dúpẹ́” lọ́wọ́ Jèhófà, o sì mọyì àwọn ọ̀dọ́ tó ti fà sínú ètò rẹ̀.​—Kól. 3:15; Jòh. 6:44; 1 Tẹs. 5:18. w21.09 11-12 ¶12-13

Friday, January 13

Pẹ̀lú àánú yìí, ojúmọ́ kan máa mọ́ wa láti ibi gíga.​—Lúùkù 1:78.

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa gan-an. Àmọ́ nígbà míì, ó lè má rọrùn fún wa láti fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa. Ó ṣe tán, àṣà wa àti ibi tá a ti wá yàtọ̀ síra, gbogbo wa la sì máa ń ṣàṣìṣe tó lè bí àwọn míì nínú. Síbẹ̀, a lè mú kí ìfẹ́ tó wà láàárín wa túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Lọ́nà wo? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fara wé bí Baba wa ọ̀run ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. (Éfé. 5:1, 2; 1 Jòh. 4:19) Ẹni tó lójú àánú máa ń wá bó ṣe máa ran àwọn míì lọ́wọ́ kó sì tù wọ́n nínú. Jésù jẹ́ ká rí i nínú ọwọ́ tó fi mú àwọn èèyàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Jòh. 5:19) Nígbà kan tí Jésù rí àwọn èrò, “àánú wọn ṣe é, torí wọ́n dà bí àgùntàn tí a bó láwọ, tí a sì fọ́n ká láìní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36) Àmọ́ kì í ṣe pé Jésù kàn káàánú wọn nìkan, ó tún wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì pèsè ìtùnú fáwọn “tó ń ṣe làálàá, tí a [sì] di ẹrù wọ̀ lọ́rùn.”​—Mát. 11:28-30; 14:14. w21.09 22 ¶10-11

Saturday, January 14

[Ọlọ́run] jẹ́ aláàánú; Ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, kò sì ní pa wọ́n run.​—Sm. 78:38.

Ó máa ń wu Jèhófà láti fàánú hàn. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé: “Àánú [Ọlọ́run] pọ̀.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ni pé aláàánú ni Ọlọ́run torí pé ó fún àwọn èèyàn aláìpé tó jẹ́ ẹni àmì òróró láǹfààní láti ní ìyè ti ọ̀run. (Éfé. 2:4-7) Àmọ́ kì í ṣe àwọn ẹni àmì òróró nìkan ni Jèhófà fàánú hàn sí. Dáfídì sọ pé: “Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá, àánú rẹ̀ sì wà lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.” (Sm. 145:9) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn, ó máa ń fàánú hàn nígbàkigbà tó bá yẹ. Torí pé kò sẹ́ni tó sún mọ́ Jèhófà bíi ti Jésù, ó mọ bó ṣe máa ń wu Jèhófà tó láti fàánú hàn. Ká má gbàgbé pé Jèhófà àti Jésù ti wà pa pọ̀ ní ọ̀run fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, kí Jésù tó wá sáyé. (Òwe 8:30, 31) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù rí bí Jèhófà ṣe fàánú hàn sí àwa èèyàn aláìpé. (Sm. 78:37-42) Torí náà, nígbà tí Jésù wá sáyé, léraléra ló máa ń kọ́ àwọn èèyàn pé Jèhófà jẹ́ aláàánú. w21.10 8-9 ¶4-5

Sunday, January 15

Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.​—Jòh. 12:28.

Jèhófà fi ohùn tó dún ketekete dáhùn àdúrà náà, ó sì ṣèlérí pé òun máa ṣe orúkọ òun lógo. Jálẹ̀ gbogbo àsìkò tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù láyé, ó ṣe orúkọ Bàbá rẹ̀ lógo. (Jòh. 17:26) Torí náà, àwa Kristẹni tòótọ́ gbà pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti máa lo orúkọ Ọlọ́run ká sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ náà. Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, Jèhófà “yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè . . . kí ó lè mú àwọn èèyàn kan jáde fún orúkọ rẹ̀ látinú wọn.” (Ìṣe 15:14) Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ yẹn gbà pé àǹfààní ńlá ni láti lo orúkọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ náà. Wọ́n lo orúkọ náà gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn àti nínú àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ. Wọ́n fi hàn pé àwọn jẹ́ èèyàn kan fún orúkọ Ọlọ́run. (Ìṣe 2:14, 21) Bákan náà lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la jẹ́ èèyàn kan fún orúkọ rẹ̀. w21.10 20-21 ¶8-10

Monday, January 16

Kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.​—Sm. 107:43.

Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ wà títí láé. Ìgbà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) ni gbólóhùn náà ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ wà títí láé fara hàn nínú Sáàmù kẹrìndínlógóje (136), ìyẹn sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an. Ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú orí yìí kà pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.” (Sm. 136:1) Ní ẹsẹ kejì sí kẹrìndínlọ́gbọ̀n (26), gbólóhùn náà “nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé” fara hàn ní ẹsẹ kọ̀ọ̀kan. Bá a ṣe ń ka àwọn ẹsẹ tó kù nínú Sáàmù kẹrìndínlógóje (136) yìí, ó yà wá lẹ́nu bá a ṣe ń rí i pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn. Gbólóhùn náà “nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé” fi dá wa lójú pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí àwa èèyàn rẹ̀ kì í yí pa dà. Ẹ ò rí i bó ṣe múnú wa dùn tó pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà ń nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀! Kì í fi àwọn tó ń sìn ín sílẹ̀, ńṣe ló máa ń dúró tì wọ́n pàápàá nígbà ìṣòro. Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ò fi wá sílẹ̀ ń jẹ́ ká máa láyọ̀, ó sì ń jẹ́ ká lókun láti máa fara da àwọn ìṣòro wa, ká sì máa rìn ní ọ̀nà ìyè.​—Sm. 31:7. w21.11 4 ¶9-10

Tuesday, January 17

Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín. Ẹ ní ìgbàgbọ́.​—Jòh. 14:1.

Ṣé àyà ẹ máa ń já tó o bá ń ronú nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhófà bá pa ìsìn èké run àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Gọ́ọ̀gù ará Mágọ́gù bá gbéjà kò wá? Ṣé ẹ̀rù tún máa ń bà ẹ́ tó o bá ń ronú nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì? Ṣé o ti bi ara ẹ rí pé, ‘tó bá dìgbà yẹn, ṣé màá lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?’ Tí irú èrò yìí bá ti wá sí ẹ lọ́kàn rí, ohun tí Jésù sọ nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín. Ẹ ní ìgbàgbọ́.” Tá a bá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára báyìí, ọkàn wa máa balẹ̀ bá a ṣe ń retí àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Tá a bá ń ronú nípa ohun tá à ń ṣe láti fara da ohun tó ń dán ìgbàgbọ́ wa wò báyìí, àá mọ bá a ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára ká lè kojú àwọn àdánwò tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú, á sì tún jẹ́ ká mọ àwọn ibi tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe. Bá a ṣe ń borí àwọn àdánwò náà, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ máa lágbára. Ìyẹn lá jẹ́ ká fara da àwọn àdánwò tá a máa kojú lọ́jọ́ iwájú. w21.11 20 ¶1-2

Wednesday, January 18

Nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, ìgbà náà ni mo di alágbára.​—2 Kọ́r. 12:10.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé kó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láìkù síbì kan. Ìmọ̀ràn yẹn wúlò fáwa náà lónìí. (2 Tím. 4:5) Àmọ́ kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Bí àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa làwọn ará wa kan ń gbé. Onírúurú ìṣòro tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni làwọn ará wa míì sì ń kojú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará wa kan ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ kí wọ́n lè pèsè ohun tí àwọn àti ìdílé wọn máa jẹ. Ó wù wọ́n kí wọ́n ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àmọ́ á ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu tó bá fi máa di òpin ọ̀sẹ̀. Àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó ni ò jẹ́ káwọn kan lè ṣe bí wọ́n ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nígbà táwọn míì ò lè jáde nílé. Ní tàwọn míì, ìrònú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan ni ò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́. Ìṣòro yòówù ká ní, Jèhófà lè fún wa lókun láti fara dà á ká lè máa sìn ín nìṣó débi tágbára wa bá gbé e dé. w21.05 20 ¶1-3

Thursday, January 19

Ẹ ò gbọ́dọ̀ . . . sọ orúkọ Ọlọ́run yín di aláìmọ́.​—Léf. 19:12.

Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń fẹ́ ká ṣe ohun tó ta ko ìjọsìn wa. Nírú ipò yìí, ó gba pé ká ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Ẹ jẹ́ ká wo ìlànà pàtàkì kan nínú Léfítíkù 19:19, ó sọ pé: ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ tó ní oríṣi òwú méjì tí wọ́n hun pọ̀.’ Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìí ló jẹ́ kí wọ́n yàtọ̀ sáwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Òfin yẹn ò kan àwa Kristẹni lónìí torí pé a lè wọ aṣọ tó ní oríṣiríṣi òwú. Àmọ́, a kì í hùwà bí àwọn èèyàn tí ìwà wọn àtohun tí wọ́n gbà gbọ́ ta ko ohun tí Bíbélì sọ. Lóòótọ́, a ṣì nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wa, a sì ń fìfẹ́ hàn sáwọn míì. Síbẹ̀, àwọn ìpinnu tá à ń ṣe nígbèésí ayé wa ń mú ká yàtọ̀ sáwọn èèyàn tí kò sin Jèhófà. Èyí ṣe pàtàkì gan-an tá a bá fẹ́ jẹ́ mímọ́.​—2 Kọ́r. 6:14-16; 1 Pét. 4:3, 4. w21.12 5 ¶14; 6 ¶16

Friday, January 20

Ẹnubodè tó lọ sí ìyè rí tóóró, ọ̀nà ibẹ̀ há.​—Mát. 7:14.

Ọ̀nà tó lọ sí ìyè ò ṣòro láti rí. Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín lóòótọ́, ẹ ó mọ òtítọ́, òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.” (Jòh. 8:31, 32) Inú wa dùn pé o ò tẹ̀ lé ohun tí ọ̀pọ̀ ń ṣe. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe lo wá bó o ṣe máa rí òtítọ́. O bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó o lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe, o sì ń fetí sáwọn ẹ̀kọ́ Jésù. O ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà fẹ́ ká pa àwọn ẹ̀kọ́ tó wá látinú ẹ̀sìn èké tì, ká sì jáwọ́ nínú àwọn àjọ̀dún tí kò bá Bíbélì mu. O tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ó lè má rọrùn láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà àti àṣà tí inú Jèhófà ò dùn sí. (Mát. 10:34-36) Ó sì lè ṣòro fún ẹ láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Síbẹ̀, o ṣe ohun tó tọ́ torí o nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ ọ̀run. O ò rí i pé inú Jèhófà máa dùn sí ẹ gan-an!​—Òwe 27:11. w21.12 22 ¶3; 23 ¶5

Saturday, January 21

Ọmọ mi, fetí sílẹ̀, kí o sì gba àwọn ọ̀rọ̀ mi.​—Òwe 4:10.

Mósè gba ìbáwí tí Jèhófà fún un lẹ́yìn tó ṣàṣìṣe, àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn sì jẹ́ fún wa. Ìgbà kan wà tó bínú gan-an tí kò sì bọlá fún Jèhófà. Ohun tí Mósè ṣe yìí ni ò jẹ́ kó wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (Nọ́ń. 20:1-13) Nígbà tí Mósè ń bẹ Jèhófà torí ìpinnu tí Jèhófà ṣe, Jèhófà sọ fún un pé: “O ò gbọ́dọ̀ bá mi sọ̀rọ̀ yìí mọ́.” (Diu. 3:23-27) Síbẹ̀, Mósè ò torí ìyẹn bínú. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gba ìbáwí tí Jèhófà fún un, Jèhófà sì jẹ́ kó máa darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìṣó. (Diu. 4:1) Àpẹẹrẹ rere ni Mósè jẹ́ fún wa tó bá dọ̀rọ̀ ká máa gba ìbáwí. Nígbà tí Jèhófà bá Mósè wí, ó gba ìbáwí, ó sì ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà nìṣó bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé òun ò ní wọ Ilẹ̀ Ìlérí. A máa jàǹfààní gan-an tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ bíi Mósè. (Òwe 4:11-13) Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ló ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn tí wọ́n sì ń gba ìbáwí. w22.02 11 ¶9-10

Sunday, January 22

Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í da omi lójú.​—Jòh. 11:35.

Nígbà òtútù lọ́dún 32 S.K., Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù tímọ́tímọ́ ṣàìsàn, ó sì kú. (Jòh. 11:3, 14) Lásárù láwọn arábìnrin méjì tórúkọ wọn ń jẹ́ Màríà àti Màtá, Jésù sì fẹ́ràn ìdílé wọn gan-an. Nígbà tí Màtá gbọ́ pé Jésù ti ń bọ̀, ó sáré lọ pàdé ẹ̀. Ẹ wo bẹ́nu Màtá á ṣe máa gbọ̀n bó ṣe ń sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú.” (Jòh. 11:21, 32, 33) Ó dájú pé nǹkan míì tó jẹ́ kí Jésù sunkún ni bó ṣe rí i tí Màríà àti Màtá ń sunkún torí ikú arákùnrin wọn. Tó bá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ ẹ tàbí ẹnì kan nínú ìdílé ẹ ti kú, ó dájú pé Jèhófà mọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣe rí lára ẹ. Jésù “ni àwòrán irú ẹni [tí Bàbá rẹ̀] jẹ́ gẹ́lẹ́.” (Héb. 1:3) Bí Jésù ṣe sunkún jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà nígbà táwọn èèyàn wa bá kú. (Jòh. 14:9) Tí èèyàn ẹ kan bá kú, mọ̀ dájú pé Jèhófà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì tún mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ. Ó máa ṣàánú ẹ, ó sì máa wo ọgbẹ́ ọkàn ẹ sàn.​—Sm. 34:18; 147:3. w22.01 15 ¶5-7

Monday, January 23

Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.​—Róòmù 10:17.

Tó o bá ń lo àkókò ẹ láti bá Jèhófà sọ̀rọ̀, tóò ń fetí sí i, tó o sì ń ronú nípa ẹ̀, wàá jàǹfààní tó pọ̀ gan-an. Àkọ́kọ́, ó máa jẹ́ kó o ṣe ìpinnu tó dáa. Bíbélì fi dá wa lójú pé “ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” (Òwe 13:20) Ìkejì, wàá túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́. Tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa ni bá a ṣe máa ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè sún mọ́ Jèhófà. Bá a bá ṣe ń bá Bàbá wa ọ̀run sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún un á máa pọ̀ sí i. Ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ mọ bá a ṣe lè kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lẹ́kọ̀ọ́ kó lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ohun tí Jésù ṣe nìyẹn. Ó sọ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ àti bó ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa, ìyẹn sì mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ olóòótọ́ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Jòh. 17:25, 26) Ìkẹta, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ lágbára. Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó o bẹ Ọlọ́run pé kó tọ́ ẹ sọ́nà, kó tù ẹ́ nínú, kó sì tì ẹ́ lẹ́yìn. Bó o ṣe ń rí i tí Jèhófà ń dáhùn àwọn àdúrà yẹn, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ ẹ ń lágbára sí i.​—1 Jòh. 5:15. w22.01 30 ¶15-17

Tuesday, January 24

Ẹ bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀.​—Kól. 3:9.

Ìdí tí Jèhófà fi sọ pé ká má gba èròkerò láyè, ká sì jáwọ́ nínú ìwà burúkú ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì fẹ́ ká gbádùn ayé wa. (Àìsá. 48:17, 18) Ó mọ̀ pé àwọn tí wọ́n bá fàyè gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lè ṣàkóbá fún ara wọn àtàwọn ẹlòmíì. Ó sì máa ń dùn ún gan-an tó bá rí i pé à ń ṣe ohun tó lè ṣàkóbá fún wa àtàwọn míì. Àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa kan lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé à ń ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé wa. (1 Pét. 4:3, 4) Wọ́n lè sọ fún wa pé a lè ṣe ohunkóhun tó bá wù wá, a ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ ohun tá a máa ṣe fún wa. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà ò lómìnira kankan. Ìdí ni pé ayé tí Sátánì ń ṣàkóso ló ń darí wọn. (Róòmù 12:1, 2) Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu ohun tóun máa ṣe, bóyá ká jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ àti ayé tí Sátánì ń darí mú ká máa hùwà àtijọ́ tàbí ká jẹ́ kí Jèhófà yí wa pa dà ká lè máa hùwà rere.​—Àìsá. 64:8. w22.03 3 ¶6-7

Wednesday, January 25

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè, ó sì ní agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ . . . ó sì lè mọ ìrònú àti ohun tí ọkàn ń gbèrò.​—Héb. 4:12.

Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, àá lè máa fojú tó tọ́ wo ìṣòro wa. Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe tu arábìnrin kan tó jẹ́ opó nínú. Alàgbà kan gbà á níyànjú pé kó ka ìwé Jóòbù pé tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, á rí ẹ̀kọ́ kọ́. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀, ṣe ló kọ́kọ́ ń dá Jóòbù lẹ́bi fún àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ. Bó ṣe ń ka ìwé náà, ṣe ló ń kìlọ̀ fún Jóòbù lọ́kàn ẹ̀ pé: “Kò yẹ kó o máa ronú ṣáá nípa ìṣòro tó o ní.” Àmọ́ ó wá rí i pé ohun tóun ń dá Jóòbù lẹ́bi fún lòun náà ń ṣe. Bó ṣe ka ìwé Jóòbù yìí mú kó tún èrò ẹ̀ ṣe, ìyẹn sì mú kó lókun láti fara da ikú ọkọ ẹ̀. Ọ̀nà míì tí Jèhófà ń gbà fún wa lókun tó sì ń ràn wá lọ́wọ́ ni pé ó máa ń lo àwọn ará wa. Pọ́ọ̀lù sọ pé àárò àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń sọ òun, ó sì wù ú pé káwọn jọ “fún ara [àwọn] ní ìṣírí.”​—Róòmù 1:11, 12. w21.05 22 ¶10-11; 24 ¶12

Thursday, January 26

Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe àjọyọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ibi tí Jèhófà bá yàn.​—Diu. 16:15.

Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé: “Kí gbogbo ọkùnrin rẹ máa fara hàn níwájú Jèhófà Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún ní ibi tó bá yàn.” (Diu. 16:16) Èyí fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi ilé àti oko wọn sílẹ̀ láìsí ẹni táá máa bá wọn ṣọ́ ọ. Àmọ́ Jèhófà ṣèlérí fún wọn pé: ‘Ilẹ̀ yín ò ní wọ ẹnikẹ́ni lójú nígbà tí ẹ bá ń gòkè lọ rí ojú Jèhófà Ọlọ́run yín.’ (Ẹ́kís. 34:24) Torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ìyẹn jẹ́ kí wọ́n lè lọ síbi àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún. Ọ̀pọ̀ àǹfààní ni wọ́n sì rí níbi àjọyọ̀ náà torí ó jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọ àwọn Òfin Jèhófà, ó jẹ́ kí wọ́n ronú lórí àwọn nǹkan rere tó ti ṣe fún wọn, ó tún fún wọn láǹfààní láti rí ìṣírí gbà bí wọ́n ṣe wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà. Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwa náà máa jàǹfààní tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa wá sípàdé déédéé. Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó, tó bá rí i pé a múra sílẹ̀ dáadáa fún ìpàdé kí ìdáhùn wa lè gbé àwọn ará ró. w22.03 22 ¶9

Friday, January 27

Ó lè ran àwọn tí à ń dán wò lọ́wọ́.​—Héb. 2:18.

Jèhófà ń dá Ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kó lè kúnjú ìwọ̀n láti di Àlùfáà Àgbà. Ohun tójú Jésù rí mú kó mọ bó ṣe nira tó láti ṣègbọràn sí Jèhófà lábẹ́ àdánwò tó lágbára. Àdánwò náà lágbára débi pé ó gbàdúrà pẹ̀lú “ẹkún tó rinlẹ̀ àti omijé.” Ẹ̀dùn ọkàn tó lékenkà tó ní mú kó lóye bí nǹkan ṣe ń rí lára wa, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ nígbàkigbà tá a bá kojú àdánwò. A mà dúpẹ́ o pé aláàánú lẹni tí Jèhófà yàn láti jẹ́ Àlùfáà Àgbà wa, ó sì “lè bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa”! (Héb. 2:17; 4:14-16; 5:7-10) Jèhófà jẹ́ kí Jésù jìyà gan-an ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè pàtàkì kan. Ìbéèrè náà ni pé: Ṣé ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí lè jẹ́ adúróṣinṣin lójú àdánwò tó lágbára? Sátánì sọ pé kò séèyàn tó máa lè jẹ́ olóòótọ́ torí pé ohun tá à ń rí gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló mú ká máa sìn ín àti pé a ò lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5) Àmọ́, Jésù jẹ́ olóòótọ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. w21.04 16-17 ¶7-8

Saturday, January 28

Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn . . . , ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.​—Mát. 28:19, 20.

Kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó lè ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ máa fi ohun tó ń kọ́ nínú Bíbélì sílò. Tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa bá ń fi ohun tó ń kọ́ sílò, ó máa dà bí “ọkùnrin kan tó ní òye” tí Jésù ṣàkàwé pé ó walẹ̀ jìn kó lè kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta. (Mát. 7:24, 25; Lúùkù 6:47, 48) Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé ẹ̀. (Máàkù 10:17-22) Jésù mọ̀ pé ó máa ṣòro fún ẹnì kan tó lọ́rọ̀ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀. (Máàkù 10:23) Síbẹ̀, ohun tí Jésù sọ pé kí ọkùnrin yẹn ṣe gan-an nìyẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Nígbà míì, a lè má fẹ́ sọ fún akẹ́kọ̀ọ́ wa pé kó ṣe àwọn àyípadà kan torí a ronú pé kò ní rọrùn fún un. (Kól. 3:9, 10) Àmọ́ tó o bá tètè bá a sọ ọ́, ìyẹn á jẹ́ kó lè tètè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.​—Sm. 141:5; Òwe 27:17. w21.06 3 ¶3, 5

Sunday, January 29

Kristi . . . fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín kí ẹ lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.​—1 Pét. 2:21.

Àpọ́sítélì Pétérù dìídì sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ àtàtà tí Jésù fi lélẹ̀ tó bá di pé ká fara da ìyà. Síbẹ̀, àwọn ọ̀nà míì wà tá a lè gbà fara wé Jésù. (1 Pét. 2:18-25) Ká sòótọ́, gbogbo ohun tí Jésù ṣe àtohun tó sọ nígbèésí ayé rẹ̀ ló jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. Ṣé òótọ́ ni pé àwa èèyàn aláìpé lè tọ ipasẹ̀ Jésù? Bẹ́ẹ̀ ni, a lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ rántí pé Pétérù ò sọ pé ká tọ ipasẹ̀ Jésù lọ́nà tó pé. Ohun tó sọ ni pé ká “tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” Tá a bá ń fara balẹ̀ tọ ipasẹ̀ Jésù, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, ṣe là ń fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù sílò pé ẹ “máa rìn bí [Jésù] ṣe rìn.” (1 Jòh. 2:6) Tá a bá ń tọ ipasẹ̀ Jésù, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè gbé ìgbésí ayé táá múnú Ọlọ́run dùn. (Jòh. 8:29) Torí náà, tá a bá ń tọ ipasẹ̀ Jésù, a máa múnú Jèhófà dùn. Ó sì dá wa lójú pé Baba wa ọ̀run máa sún mọ́ gbogbo àwọn tó ń sapá láti di ọ̀rẹ́ rẹ̀.​—Jém. 4:8. w21.04 3 ¶4-6

Monday, January 30

Inú Jèhófà ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀.​—Sm. 149:4.

Jèhófà máa ń kíyè sí àwọn ànímọ́ rere tá a ní, ó mọ̀ pé ó máa ń wù wá láti ṣe ohun tó dáa, ó sì máa ń mú ká sún mọ́ òun. Torí náà, tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí i, kò ní fi wá sílẹ̀ láé àti láéláé! (Jòh. 6:44) Tó bá dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń tì wá lẹ́yìn, tọkàntara làá fi máa ṣèfẹ́ rẹ̀ láìka ìṣòro yòówù ká kojú sí. Lọ́wọ́ kejì, tá a bá ń ṣiyèméjì pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, “agbára [wa] ò ní tó nǹkan.” (Òwe 24:10) Tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, tá a sì ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa, wẹ́rẹ́ báyìí la máa kó sọ́wọ́ Sátánì. (Éfé. 6:16) Àwọn ará wa kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ àwọn, ìyẹn sì ti mú kí ìgbàgbọ́ wọn máa jó àjórẹ̀yìn. Kí ló yẹ ká ṣe tírú èrò bẹ́ẹ̀ bá wá sí wa lọ́kàn? Ṣe ló yẹ ká gbé e kúrò lọ́kàn kíá! O lè bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè gbé ‘àwọn ohun tó ń dà ẹ́ lọ́kàn rú’ kúrò, kó sì jẹ́ kó o ní ‘àlàáfíà Ọlọ́run táá máa ṣọ́ ọkàn rẹ àti agbára ìrònú rẹ.’ (Sm. 139:23; àlàyé ìsàlẹ̀; Fílí. 4:6, 7) Sì máa rántí pé ìwọ nìkan kọ́ lo nírú èrò yìí. w21.04 20 ¶1; 21 ¶4-6

Tuesday, January 31

Ọlọ́run ni ẹni tó ń . . . mú kó wù yín láti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń fún yín ní agbára láti ṣe é.​—Fílí. 2:13.

Báwo lo ṣe di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n wàásù fún ẹ. Ó lè jẹ́ àwọn òbí ẹ tàbí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́. Ó sì lè jẹ́ ọmọ ilé ìwé ẹ tàbí Ẹlẹ́rìí kan tó ń wàásù láti ilé dé ilé ló sọ “ìhìn rere” fún ẹ. (Máàkù 13:10) Lẹ́yìn náà, wọ́n lo ọ̀pọ̀ àkókò láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, o rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ìyẹn sì mú kíwọ náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ní báyìí tí Jèhófà ti fà ẹ́ sínú òtítọ́, tó o sì ti di ọmọlẹ́yìn Jésù, o nírètí láti gbé títí láé. (Jòh. 6:44) Kò sí àní-àní pé o mọyì bí Jèhófà ṣe lo ẹnì kan láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tó sì jẹ́ kó o di ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Òun. Ní báyìí tó o ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ìwọ náà láǹfààní láti ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè nírètí àtiwà láàyè títí láé. Ó lè rọrùn fún àwọn kan lára wa láti máa wàásù láti ilé dé ilé, àmọ́ kó ṣòro fún wọn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. w21.07 2 ¶1-2

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́