February
Wednesday, February 1
Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é.—Sm. 145:18.
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì fẹ́ ká máa láyọ̀. Jèhófà wà nítòsí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, ó sì máa ń mọ̀ tínú wa ò bá dùn tàbí tá a rẹ̀wẹ̀sì. (Sm. 145:18, 19) Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ran Èlíjà lọ́wọ́ nígbà tó rẹ̀wẹ̀sì. Àsìkò tí nǹkan ò rọgbọ nílẹ̀ Ísírẹ́lì ni wòlíì yẹn gbáyé. Àwọn ọ̀tá tó wà nípò àṣẹ ń ṣe inúnibíni tó gbóná janjan sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, kódà wọ́n dìídì dájú sọ Èlíjà. (1 Ọba 19:1, 2) Ohun míì tó ṣeé ṣe kó dá kún ìṣòro Èlíjà ni pé ó ronú pé òun nìkan ni wòlíì Jèhófà tó ṣẹ́ kù. (1 Ọba 19:10) Jèhófà tètè dá sọ́rọ̀ Èlíjà. Ó rán áńgẹ́lì kan sí i láti tù ú nínú, kó sì fi í lọ́kàn balẹ̀ pé òun nìkan kọ́ ni ìránṣẹ́ Jèhófà tó ṣẹ́ kù, àwọn míì náà wà tí wọ́n ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà! (1 Ọba 19:5, 18) Jésù wá fi àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ lọ́kàn balẹ̀, ó sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé wọ́n máa ní ọ̀pọ̀ àwọn ará tó máa dà bí ọmọ ìyá. (Máàkù 10:29, 30) Bákan náà, Jèhófà Baba wa ọ̀run ṣèlérí pé òun máa ti gbogbo àwọn tó ń sin òun lẹ́yìn.—Sm. 9:10. w21.06 8-9 ¶3-4
Thursday, February 2
Ẹni tó bá wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run máa ń fetí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Jòh. 8:47.
Ọ̀pọ̀ ò nífẹ̀ẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé àwọn ẹ̀kọ́ tá a mú látinú Bíbélì ń tú àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ èké wọn. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn pé Ọlọ́run ń dá àwọn èèyàn lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ èké yìí dẹ́rù ba àwọn ọmọ ìjọ wọn kí wọ́n lè máa darí wọn síbi tí wọ́n bá fẹ́. Àmọ́ àwa tá à ń sin Jèhófà mọ̀ pé Ọlọ́run ìfẹ́ ni, ìdí nìyí tá a fi ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé kò sí ọ̀run àpáàdì. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tún máa ń kọ́ni pé ọkàn èèyàn kì í kú, àmọ́ à ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹ̀kọ́ yìí ò bá Bíbélì mu torí pé tí ọkàn èèyàn ò bá kú, kò ní sídìí pé Jèhófà ń jí àwọn òkú dìde. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn gbà pé ohun gbogbo ni Ọlọ́run ti kádàrá, àmọ́ àwa ń kọ́ni pé àwa èèyàn lè pinnu bóyá a máa sin Ọlọ́run tàbí a ò ní sìn ín. Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí tá a bá tú àṣírí wọn? Lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe ni wọ́n máa ń gbaná jẹ! Tá a bá nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, a gbọ́dọ̀ gba ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ gbọ́. (Jòh. 8:45, 46) A ò ní ṣe bíi Sátánì tí ò dúró nínú òtítọ́, a kì í sì í ṣe ohunkóhun tó bá ta ko ohun tá a gbà gbọ́. (Jòh. 8:44) Ọlọ́run fẹ́ káwa èèyàn ẹ̀ “kórìíra ohun búburú” ká sì “rọ̀ mọ́ ohun rere” bíi ti Jésù.—Róòmù 12:9; Héb. 1:9. w21.05 10 ¶10-11
Friday, February 3
Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, ó sì máa sá kúrò lọ́dọ̀ yín.—Jém. 4:7.
Kí la lè ṣe tá a bá kíyè sí i pé ìgbéraga ti ń wọ̀ wá lẹ́wù tàbí pé a ti ń ṣojúkòkòrò? Ṣe ló yẹ ká tètè ṣàtúnṣe! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn tí Èṣù ti ‘mú láàyè’ lè jàjà bọ́ lọ́wọ́ ìdẹkùn rẹ̀. (2 Tím. 2:26) Má gbàgbé pé Jèhófà lágbára ju Sátánì lọ. Torí náà, tó o bá jẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́, wàá bọ́ lọ́wọ́ ìdẹkùn tàbí páńpẹ́ Sátánì. Ohun tó dáa jù ni pé ká má tiẹ̀ kó sọ́wọ́ Sátánì rárá dípò ká máa wá bá a ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ ìdẹkùn rẹ̀. Àmọ́ o, Jèhófà nìkan ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní kó sí i lọ́wọ́. Torí náà, máa bẹ Jèhófà lójoojúmọ́ pé kó jẹ́ kó o mọ̀ bóyá o ti fẹ́ máa gbéra ga tàbí ṣojúkòkòrò. (Sm. 139:23, 24) Má jẹ́ kí Sátánì rí ẹ mú! Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń dọdẹ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà. Àmọ́ láìpẹ́, wọ́n máa jù ú sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, níkẹyìn wọ́n á pa á run. (Ìfi. 20:1-3, 10) Ṣe ló ń ṣe wá bíi pé kọ́jọ́ náà ti dé. Àmọ́ títí dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká máa wà lójúfò ká má bàa kó sínú páńpẹ́ rẹ̀. Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí Sátánì má bàa fi ìgbéraga tàbí ojúkòkòrò dẹkùn mú ẹ. Torí náà, pinnu pé wàá “dojú ìjà kọ Èṣù.” Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ‘ó máa sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ.’ w21.06 19 ¶15-17
Saturday, February 4
Ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde láti bá a kórè.—Mát. 9:38.
Inú Jèhófà máa ń dùn tí ẹnì kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì ń sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn míì. (Òwe 23:15, 16) Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà máa dùn gan-an bó ṣe ń rí i táwa èèyàn ẹ̀ ń fìtara wàásù tá a sì ń kọ́ni lónìí! Bí àpẹẹrẹ, láìka bí àrùn Corona ṣe gbalẹ̀ gbòde lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2020, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́jọ (7,705,765) la darí, ìyẹn mú kí àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ (241,994) ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn yìí náà máa kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n á sì sọ wọ́n dọmọ ẹ̀yìn. (Lúùkù 6:40) Ó dájú pé inú Jèhófà ń dùn bó ṣe ń rí i tá à ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Kò rọrùn láti sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ẹni tuntun kí wọ́n lè wá jọ́sìn Òun. Torí náà, ṣé o lè pinnu pé wàá bẹ̀rẹ̀ sí í darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ó kéré tán? Tó o bá ń lo gbogbo àǹfààní tó o ní láti wàásù, ó máa yà ẹ́ lẹ́nu pé wàá rí àwọn tó máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. w21.07 6-7 ¶14-16
Sunday, February 5
Nítorí ìfẹ́ tí mo ní fún ilé Ọlọ́run mi, mo fi wúrà àti fàdákà sílẹ̀ látinú àwọn ohun iyebíye mi fún ilé Ọlọ́run mi.—1 Kíró. 29:3.
Ọba Dáfídì fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó àtàwọn nǹkan míì tó ní ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà. (1 Kíró. 22:11-16) Tá ò bá tiẹ̀ lókun láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé ètò Ọlọ́run mọ́, a ṣì lè lo owó wa àtàwọn nǹkan míì tá a ní láti ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn débi tágbára wa bá gbé e dé. Bákan náà, a lè fi àwọn ìrírí tá a ní fún àwọn ọ̀dọ́ lókun kí wọ́n lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àtàtà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ pé kéèyàn jẹ́ ọ̀làwọ́. Pọ́ọ̀lù ní kí òun àti Tímótì jọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì pa pọ̀, ó sì kọ́ ọ̀dọ́kùnrin náà ní gbogbo ohun tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. (Ìṣe 16:1-3) Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ran Tímótì lọ́wọ́ kó lè já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (1 Kọ́r. 4:17) Lẹ́yìn náà, Tímótì lo àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ́ ọ láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ káwọn náà lè já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. w21.09 12 ¶14-15
Monday, February 6
Owú àti wàhálà wà láàárín yín.—1 Kọ́r. 3:3.
Kí la lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Àpólò àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù? Àwọn méjèèjì mọ Ìwé Mímọ́ dunjú, wọ́n mọ̀ọ̀yàn kọ́ gan-an, àwọn ará sì mọ̀ wọ́n dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn méjèèjì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn, síbẹ̀ wọn ò jowú ara wọn. (Ìṣe 18:24) Kódà, lẹ́yìn tí Àpólò fi Kọ́ríńtì sílẹ̀, Pọ́ọ̀lù tún rọ̀ ọ́ pé kó pa dà síbẹ̀. (1 Kọ́r. 16:12) Ó dájú pé ọ̀nà tó dáa ni Àpólò gbà lo ẹ̀bùn tó ní, ó wàásù ìhìn rere, ó sì fún àwọn ará lókun. Yàtọ̀ síyẹn, onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni. Bí àpẹẹrẹ, kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé ó bínú nígbà tí Ákúílà àti Pírísílà “ṣàlàyé ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tó túbọ̀ péye.” (Ìṣe 18:24-28) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ àwọn iṣẹ́ rere tí Àpólò ṣe, àmọ́ kò jowú ẹ̀. Ó hàn nínú ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kò sì jọ ara ẹ̀ lójú.—1 Kọ́r. 3:4-6. w21.07 18-19 ¶15-17
Tuesday, February 7
Ọ̀pọ̀ èèyàn [máa] di olódodo.—Róòmù 5:19.
Ádámù àti Éfà mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ìdí nìyẹn tó fi kọ̀ wọ́n lọ́mọ. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ wọn? Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó ṣètò bí àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn ṣe máa pa dà di ara ìdílé òun. Ètò tó ṣe ni pé ó fi Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo rà wá pa dà. (Jòh. 3:16) Ìràpadà yìí ló mú kó ṣeé ṣe fáwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin láti di ọmọ Ọlọ́run. (Róòmù 8:15-17; Ìfi. 14:1) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olóòótọ́ míì ló ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n máa ní àǹfààní láti di ara ìdílé Ọlọ́run lẹ́yìn tí wọ́n bá yege ìdánwò ìkẹyìn tó máa wáyé níparí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. (Sm. 25:14; Róòmù 8:20, 21) Ní báyìí, wọ́n ti ń pe Jèhófà Ẹlẹ́dàá wọn ní “Baba.” (Mát. 6:9) Bákan náà, àwọn tó bá jíǹde máa láǹfààní láti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ṣe. Àwọn tó bá sì ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ máa di ara ìdílé rẹ̀. w21.08 5 ¶10-11
Wednesday, February 8
Ẹ . . . máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.—Fílí. 1:10.
Jèhófà gbé iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ ọdún ló sì fi ṣe iṣẹ́ náà torí ohun tó kà sí pàtàkì jù nígbèésí ayé ẹ̀ nìyẹn. Ó wàásù “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” (Ìṣe 20:20) Kódà, gbogbo ìgbà ni Pọ́ọ̀lù máa ń wàásù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń dúró de àwọn tí wọ́n jọ ń wàásù ní Áténì, ó wàásù fún àwọn gbajúmọ̀ kan níbẹ̀, àwọn kan sì fetí sí i. (Ìṣe 17:16, 17, 34) Kódà nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà nínú “ẹ̀wọ̀n,” ó wàásù fún àwọn tó wà pẹ̀lú ẹ̀. (Fílí. 1:13, 14; Ìṣe 28:16-24) Pọ́ọ̀lù lo àkókò ẹ̀ lọ́nà tó dáa jù lọ. Ó máa ń pe àwọn míì pé káwọn jọ lọ wàásù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó rìnrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ àkọ́kọ́, ó mú Jòhánù Máàkù dání, nígbà tó sì lọ lẹ́ẹ̀kejì, ó mú Tímótì dání. (Ìṣe 12:25; 16:1-4) Kò sí àní-àní pé Pọ́ọ̀lù dá àwọn ọkùnrin yìí lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe ń ṣètò nǹkan nínú ìjọ, bí wọ́n á ṣe máa fìfẹ́ bójú tó àwọn ará àti bí wọ́n ṣe máa di olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́.—1 Kọ́r. 4:17. w22.03 27 ¶5-6
Thursday, February 9
[Ọlọ́run] kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.—Ìṣe 17:27.
Àwọn kan ò gbà pé Ẹlẹ́dàá wà torí pé ohun tí wọ́n rí nìkan ni wọ́n gbà gbọ́. Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà tí wọn ò rí, síbẹ̀ tí wọ́n gbà pé ó wà, irú bí agbára òòfà. Ìgbàgbọ́ tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ dá lórí ẹ̀rí tó ṣe kedere nípa “àwọn ohun gidi tí a kò rí.” (Héb. 11:1) Ó máa ń gba àkókò àti ìsapá ká tó lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò sì ráyè irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ rárá. Ẹni tí ò bá ṣèwádìí àwọn ẹ̀rí tó ṣe kedere yìí lè gbà pé kò sí Ọlọ́run. Ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ṣe mú kí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan. Àmọ́ àwọn kan gbà pé kò sí Ẹlẹ́dàá torí pé ohun tí wọ́n fi kọ́ wọn ní yunifásítì nìyẹn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn ló ti wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo wa la gbọ́dọ̀ mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára, bóyá a kàwé tàbí a ò kàwé. w21.08 14 ¶1; 15-16 ¶6-7
Friday, February 10
Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá, àánú rẹ̀ sì wà lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.—Sm. 145:9.
Jésù sọ àpèjúwe kan nípa ọmọ onínàákúnàá ká lè mọ bó ṣe máa ń wu Jèhófà tó láti fàánú hàn. Ọmọ náà fi ilé sílẹ̀, ó wá lọ ń ‘gbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla, ó sì lo àwọn ohun ìní rẹ̀ nílòkulò.’ (Lúùkù 15:13) Nígbà tó yá, ó jáwọ́ nínú ìwàkiwà tó ń hù, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì pa dà sílé. Kí ni bàbá ẹ̀ wá ṣe? Jésù sọ pé: “Bó ṣe ń bọ̀ ní òkèèrè ni bàbá rẹ̀ tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó wá sáré lọ dì mọ́ ọn, ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu.” Bàbá yẹn ò kan ọmọ ẹ̀ lábùkù. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló fàánú hàn sí i, ó dárí jì í, ó sì gbà á pa dà sílé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó burú gan-an ni ọmọ náà ṣe, bàbá ẹ̀ dárí jì í torí pé ó ronú pìwà dà. Jèhófà ni Bàbá aláàánú inú àpèjúwe yẹn ṣàpẹẹrẹ. Jésù lo àpèjúwe yìí ká lè mọ bó ṣe máa ń wu Jèhófà tó láti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.—Lúùkù 15:17-24. w21.10 8 ¶4; 9 ¶6
Saturday, February 11
Ọlọ́run . . . yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ kí ó lè mú àwọn èèyàn kan jáde fún orúkọ rẹ̀ látinú wọn.—Ìṣe 15:14.
Lónìí, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn olórí ẹ̀sìn ti ṣe káwọn èèyàn má bàa mọ̀ pé Ọlọ́run ní orúkọ tiẹ̀. Wọ́n ti yọ orúkọ náà kúrò nínú àwọn Bíbélì wọn, kódà àwọn kan tiẹ̀ ṣòfin pé ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ lo orúkọ náà nínú ṣọ́ọ̀ṣì wọn. Ó hàn gbangba pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣe orúkọ náà lógo. Nínú gbogbo ẹ̀sìn tó wà láyé, àwa là ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ náà gan-an! Àwọn nǹkan tá à ń ṣe yìí ló fi hàn pé àwa gangan ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Àìsá. 43:10-12) A ti tẹ Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí iye ẹ̀ ju mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ogójì (240,000,000) lọ. Bíbélì yìí sì lo orúkọ Jèhófà láwọn ibi táwọn atúmọ̀ Bíbélì kan ti yọ ọ́ kúrò. Yàtọ̀ síyẹn, à ń tẹ àwọn ìwé tó ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run jáde ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ! w21.10 20-21 ¶9-10
Sunday, February 12
Tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ bá di aláìní láàárín rẹ . . . , o ò gbọ́dọ̀ mú kí ọkàn rẹ le tàbí kí o háwọ́ sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní.—Diu. 15:7.
Tá a bá ń ran àwọn ará tó jẹ́ aláìní lọ́wọ́, à ń jọ́sìn Jèhófà nìyẹn. Jèhófà ṣèlérí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọ́n bá ṣojúure sáwọn aláìní, òun máa bù kún wọn. (Diu. 15:10) Gbogbo ìgbà tá a bá ran arákùnrin tàbí arábìnrin wa kan tó jẹ́ aláìní lọ́wọ́, inú Jèhófà máa ń dùn torí ó mọ̀ pé òun là ń ṣe é fún. (Òwe 19:17) Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ará ní Fílípì fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Pọ́ọ̀lù nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, ó pè é ní “ẹbọ tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tó sì wu Ọlọ́run gidigidi.” (Fílí. 4:18) Ṣé ìwọ náà lè wo àwọn ará ìjọ tó o wà, kó o sì bi ara ẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ẹnì kan wà níbẹ̀ tí mo lè ràn lọ́wọ́?’ Inú Jèhófà máa dùn tó bá ń rí i pé à ń lo àkókò wa, okun wa, àwọn ẹ̀bùn tá a ní, àtàwọn ohun ìní wa láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Torí náà, tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, à ń jọ́sìn Jèhófà nìyẹn. (Jém. 1:27) Ìjọsìn tòótọ́ máa ń gba àkókò àti ìsapá. Àmọ́ kò nira. (1 Jòh. 5:3) Kí nìdí? Ìdí ni pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló mú ká máa jọ́sìn ẹ̀, a sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa. w22.03 24 ¶14-15
Monday, February 13
Ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn èèyàn burúkú àtàwọn èèyàn rere.—Mát. 5:45.
Ká tó lè máa fàánú hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan lè ní àìsàn kan tó le gan-an. Kì í sábà sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro ẹ̀, àmọ́ inú ẹ̀ máa dùn gan-an tẹ́nì kan bá ràn án lọ́wọ́. A lè bi ara wa pé, ṣé inú ẹ̀ máa dùn tá a bá bá a dáná, tá a sì bá a tún ilé ṣe? Ká sọ pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ arákùnrin kan, kí la lè ṣe? Láìjẹ́ kó mọ̀, ṣé a lè fi owó díẹ̀ ránṣẹ́ sí i kó lè fi gbéra títí táá fi ríṣẹ́ míì? Kò yẹ ká dúró dìgbà táwọn ará bá ní ká ran àwọn lọ́wọ́ ká tó ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ṣe là ń fìwà jọ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ojoojúmọ́ ló ń mú kí oòrùn ràn láìjẹ́ pé a béèrè fún un. Gbogbo èèyàn ni ìtànṣán tó ń jáde lára oòrùn ń ṣe láǹfààní títí kan àwọn tí ò sin Jèhófà. Ṣẹ́yin náà gbà pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó máa pèsè gbogbo nǹkan yìí fún wa? A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ń fàánú hàn sí wa, ó sì ń pèsè gbogbo ohun tá a nílò. w21.09 22-23 ¶12-13
Tuesday, February 14
Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè ọ́ pọ̀ gidigidi.—Sm. 86:5.
Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ ló ń mú kó dárí jì wá. Tí Jèhófà bá rí i pé ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ronú pìwà dà, tí kò sì pa dà dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ máa mú kó dárí ji ẹni náà. Dáfídì sọ nípa Jèhófà pé: “Kò fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa hùwà sí wa, kò sì fi ìyà tó yẹ àṣìṣe wa jẹ wá.” (Sm. 103:8-11) Dáfídì mọ bó ṣe máa ń rí tí ìbànújẹ́ bá dorí ẹni kodò torí ẹ̀rí ọkàn tó ń dáni lẹ́bi. Àmọ́ ó tún mọ̀ pé Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini.” Kí ló ń mú kí Jèhófà máa dárí jini? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní. Bí Dáfídì ṣe sọ nínú àdúrà rẹ̀ ló rí, Jèhófà máa ń dárí jini torí pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè é pọ̀ gidigidi. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ó yẹ ká kábàámọ̀ ohun tá a ṣe, kò sì sóhun tó burú níbẹ̀. Ìyẹn máa jẹ́ ká ronú pìwà dà, ká sì gbégbèésẹ̀ láti ṣàtúnṣe. w21.11 5 ¶11-12
Wednesday, February 15
Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́.—Mát. 6:9.
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ̀, ó sì fẹ́ kí gbogbo wa máa bọ̀wọ̀ fún un. (Àìsá. 42:8) Àmọ́ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ọdún báyìí ni wọ́n ti ń kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀. (Sm. 74:10, 18, 23) Èṣù tó túmọ̀ sí “Abanijẹ́” ló kọ́kọ́ kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. Ó fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé kò fún Ádámù àti Éfà ní ohun tí wọ́n nílò. (Jẹ́n. 3:1-5) Àtìgbà yẹn ni wọ́n ti ń fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò fún àwa èèyàn ní ohun tá a nílò gan-an. Inú Jésù ò dùn bó ṣe ń rí i táwọn èèyàn ń kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso ayé àtọ̀run, ìṣàkóso rẹ̀ ló sì dáa jù. (Ìfi. 4:11) Àmọ́ Èṣù ti gbìyànjú láti mú káwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn ronú pé Ọlọ́run ò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Láìpẹ́, ọ̀rọ̀ náà máa yanjú pátápátá. Ìgbà yẹn ló máa ṣe kedere pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run àti pé Ìjọba ẹ̀ nìkan ló lè mú àlàáfíà wá. w21.07 9 ¶5-6
Thursday, February 16
Màá yọ̀ gidigidi nínú Jèhófà; inú mi yóò dùn nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.—Háb. 3:18.
Ojúṣe olórí ìdílé kan ni láti pèsè oúnjẹ, aṣọ àti ilé fún ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀. Ṣé nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa fún ẹ báyìí, tó ò sì lówó lọ́wọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé nǹkan máa nira fún ẹ nìyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fún ẹ báyìí, síbẹ̀ o ṣì lè lo àkókò yìí láti mú kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára. Gbàdúrà kó o sì ka ohun tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:25-34, kó o wá ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó o kà. O tún lè ronú nípa ìrírí àwọn ará tó fi hàn pé Jèhófà máa ń pèsè fún àwọn tó pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (1 Kọ́r. 15:58) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó ṣe ran àwọn ará yẹn lọ́wọ́. Ó mọ àwọn nǹkan tó o nílò, á sì pèsè wọn fún ẹ. Bí ìwọ náà ṣe ń rọ́wọ́ Jèhófà láyé ẹ, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ máa lágbára, wàá sì lè kojú àwọn àdánwò tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. w21.11 20 ¶3; 21 ¶6
Friday, February 17
Tí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀, a ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi.—1 Jòh. 2:1.
Ọ̀rọ̀ ìràpadà ló mú kí ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni lágbára gan-an. Bí àpẹẹrẹ, wọn ò dẹ́kun àtimáa wàásù láìka àtakò sí, wọ́n sì fara da onírúurú àdánwò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Àpẹẹrẹ kan ni àpọ́sítélì Jòhánù. Ó fòótọ́ ọkàn wàásù nípa Kristi àti ìràpadà fún ohun tó ju ọgọ́ta (60) ọdún lọ. Nígbà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún, ìjọba Róòmù kà á sí ẹni tó lè dá wàhálà sílẹ̀ nílùú. Torí náà, wọ́n fi í sẹ́wọ̀n ní erékùṣù Pátímọ́sì. Kí lẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀? Ó sọ pé: “Mò ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, mo sì ń jẹ́rìí nípa Jésù.” (Ìfi. 1:9) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jòhánù jẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ ká nígbàgbọ́, ká sì lẹ́mìí ìfaradà! Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jòhánù sọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Jésù tó àti bó ṣe mọyì ìràpadà. Nínú àwọn ìwé tó kọ, ó ju ọgọ́rùn-ún (100) ìgbà lọ tó tọ́ka sí ìràpadà tàbí àǹfààní tí ìràpadà ń mú wá. (1 Jòh. 2:2) Ó dájú pé Jòhánù mọyì ìràpadà gan-an. w21.04 17 ¶9-10
Saturday, February 18
Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣépè fún adití tàbí kí ẹ fi ohun ìdènà síwájú afọ́jú.—Léf. 19:14.
Jèhófà fẹ́ káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ máa fi inúure hàn sáwọn tó ní àìlera. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣépè fún adití. Tẹ́nì kan bá ń ṣépè fún adití tàbí tó ń sọ ohun tí kò dáa sí i, ṣe ló ń fẹ́ kí ohun burúkú ṣẹlẹ̀ sí i. Ìyẹn mà burú gan-an o! Torí pé kò gbọ́ nǹkan táwọn èèyàn ń sọ nípa òun, kò ní lè gbèjà ara ẹ̀. Bákan náà, Léfítíkù 19:14 sọ pé àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ò gbọ́dọ̀ “fi ohun ìdènà síwájú afọ́jú.” Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ní àìlera sọ pé: “Wọ́n máa ń yàn wọ́n jẹ, wọ́n sì máa ń hùwà ìkà sí wọn ní apá Ìlà Oòrùn ayé.” Àwọn èèyàn kan tí ò láàánú máa ń gbé ohun ìdènà síwájú àwọn afọ́jú kí wọ́n lè ṣe wọ́n léṣe tàbí kí wọ́n lè máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Ẹ ò rí i pé ìwà ìkà nìyẹn! Àṣẹ tí Jèhófà pa fáwọn èèyàn rẹ̀ yìí jẹ́ kí wọ́n rí i pé ó yẹ kí wọ́n máa fi àánú hàn sí àwọn tó ní àìlera. w21.12 8-9 ¶3-4
Sunday, February 19
Ẹ̀rù ba Jékọ́bù gan-an, ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀.—Jẹ́n. 32:7.
Ẹ̀rù ń ba Jékọ́bù gan-an, ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀ torí ó rò pé ẹ̀gbọ́n òun ṣì ń bínú sí òun. Torí náà, ó gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ó fi ẹ̀bùn rẹpẹtẹ ránṣẹ́ sí Ísọ̀. (Jẹ́n. 32:9-15) Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, nígbà tí Jékọ́bù àti Ísọ̀ ríra lójúkojú, ó ṣe ohun tó fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún ẹ̀gbọ́n ẹ̀. Ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló tẹrí ba fún Ísọ̀! Torí pé Jékọ́bù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tó sì bọ̀wọ̀ fún ẹ̀gbọ́n ẹ̀, ìyẹn ló jẹ́ kó wá àlàáfíà pẹ̀lú ẹ̀. (Jẹ́n. 33:3, 4) A kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nínú ohun tí Jékọ́bù ṣe nígbà tó lọ bá Ísọ̀. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jékọ́bù ní mú kó bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣe ohun tó bá àdúrà ẹ̀ mu, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti wá àlàáfíà pẹ̀lú Ísọ̀. Nígbà tí wọ́n pàdé, Jékọ́bù ò bẹ̀rẹ̀ sí í jiyàn pẹ̀lú Ísọ̀ nípa ẹni tó jẹ̀bi tàbí ẹni tó jàre. Ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ ni bó ṣe máa wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin ẹ̀. Ṣé wàá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jékọ́bù?—Mát. 5:23, 24. w21.12 25 ¶11-12
Monday, February 20
Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.—1 Jòh. 3:20.
Nígbà tó o bá ń ronú nípa ìràpadà tí Jésù san fún ẹ, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ‘kì í ṣe irú èèyàn bíi tèmi ni Jésù máa kú fún.’ Kí ló lè mú kó ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀? Torí pé aláìpé ni wá, ọkàn wa lè tàn wá jẹ, ó lè mú ká máa ronú pé a ò wúlò tàbí pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ wa. (1 Jòh. 3:19) Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé “Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ.” Òótọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro ni pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì máa dárí jì ẹ́ kódà tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kò nífẹ̀ẹ́ ẹ tàbí pé kò lè dárí jì ẹ́. Ó ṣe pàtàkì ká máa wo ara wa bí Jèhófà ṣe ń wò wá, pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì ní fi wá sílẹ̀. Èyí gba pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo, ká sì máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ará. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe àwọn nǹkan yìí? Á jẹ́ kó o túbọ̀ mọ Jèhófà. Á jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ. Tó o bá ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, á jẹ́ kó o máa ronú lọ́nà tó tọ́.—2 Tím. 3:16. w21.04 23-24 ¶12-13
Tuesday, February 21
Màá ké pe Ọlọ́run, yóò sì gbọ́ mi.—Sm. 77:1.
Ká tó lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ohun tá a máa ṣe ju ká kàn ní ìmọ̀ lọ. Ó yẹ ká máa ṣàṣàrò lórí ohun táà ń kọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ẹni tó kọ Sáàmù 77. Ìdààmú bá a torí ó rò pé òun àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù ti pàdánù ojú rere Jèhófà. Àwọn nǹkan tó ń rò yìí ni ò jẹ́ kó lè sùn lóru. (Ẹsẹ 2-8) Kí ló wá ṣe? Ó sọ fún Jèhófà pé: “Màá ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ, màá sì ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun tí o ṣe.” (Ẹsẹ 12) Ó dájú pé onísáàmù náà mọ ohun tí Jèhófà ti ṣe fáwọn èèyàn ẹ̀ sẹ́yìn, àmọ́ ó ṣì ń ṣiyèméjì pé: “Ṣé Ọlọ́run ti gbàgbé láti ṣojú rere ni, àbí, ṣé ìbínú rẹ̀ ti dínà àánú rẹ̀ ni?” (Ẹsẹ 9) Onísáàmù náà ronú lórí iṣẹ́ Jèhófà, ó sì mọ̀ pé Jèhófà ti fàánú àti ìyọ́nú hàn sáwọn èèyàn ẹ̀ sẹ́yìn. (Ẹsẹ 11) Kí ni gbogbo àṣàrò tó ṣe yẹn yọrí sí? Ó wá dá onísáàmù náà lójú pé Jèhófà ò ní pa àwọn èèyàn Ẹ̀ tì. (Ẹsẹ 15) w22.01 30-31 ¶17-18
Wednesday, February 22
Lójú rẹ̀, gbogbo wọn wà láàyè.—Lúùkù 20:38.
Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà táwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin bá kú? Ó máa ń wù ú gan-an pé kóun tún pa dà rí wọn! (Jóòbù 14:15) Fojú inú wo báá ṣe máa wu Jèhófà láti tún rí Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Jém. 2:23) Tàbí Mósè tó bá sọ̀rọ̀ ní “ojúkojú.” (Ẹ́kís. 33:11) Ẹ sì wo báá ṣe máa wu Jèhófà tó láti gbọ́ ohùn Dáfídì àtàwọn onísáàmù míì bí wọ́n ṣe ń fayọ̀ kọrin ìyìn sí i! (Sm. 104:33) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yìí ló ti kú, Jèhófà ò gbàgbé wọn. (Àìsá. 49:15) Ó rántí bí gbogbo wọn ṣe rí àti ànímọ́ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní. Lọ́jọ́ kan, á jí wọn dìde, á tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn, á sì tún máa fetí sí àdúrà wọn. Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà ń ṣàárò èèyàn ẹ kan tó ti kú, jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ yìí tù ẹ́ nínú, kó sì fún ẹ lókun. Nígbà tí Sátánì mú kí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà mọ̀ pé nǹkan á burú gan-an kó tó di pé ó máa pa dà bọ̀ sípò. Jèhófà kórìíra ìwà ìkà, ìrẹ́jẹ àti ìwà ipá tó kúnnú ayé lónìí. w21.07 10 ¶11; 12 ¶12
Thursday, February 23
[Ó] yẹ kí ìfẹ́ wa . . . jẹ́ ní ìṣe àti òtítọ́.—1 Jòh. 3:18.
Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, ṣe là ń fi hàn pé a mọyì ìràpadà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kì í ṣe àwa nìkan ni Jésù kú fún, ó kú fún gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin náà. Ti pé Jésù kú fún wọn fi hàn pé wọ́n ṣeyebíye lójú rẹ̀. (1 Jòh. 3:16-18) Ohun tá a bá ṣe fún àwọn ará wa ló máa fi hàn bóyá a nífẹ̀ẹ́ wọn tàbí a ò nífẹ̀ẹ́ wọn. (Éfé. 4:29, 31–5:2) Bí àpẹẹrẹ, a máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣàìsàn, tí wọ́n ń kojú àdánwò tàbí tí àjálù dé bá wọn. Àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe tí ẹnì kan nínú ìjọ bá sọ ọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun kan tó dùn wá? Ṣé o máa ń di ẹni tó bá ṣẹ̀ ẹ́ sínú? (Léf. 19:18) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò pé: “Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà, kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì. Bí Jèhófà ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.” (Kól. 3:13) Gbogbo ìgbà tá a bá dárí ji arákùnrin tàbí arábìnrin kan, ṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a mọyì ìràpadà náà lóòótọ́. w21.04 18 ¶12-13
Friday, February 24
Ẹ máa fi [ẹ̀bùn yín] ṣe ìránṣẹ́ fún ara yín.—1 Pét. 4:10.
A lè máa ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ká sì ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé àṣeyọrí èyíkéyìí tá a bá ṣe, Jèhófà ló mú kó ṣeé ṣe. Ẹ̀kọ́ míì tún wà tá a lè kọ́ lára Àpólò àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ẹ̀kọ́ náà ni pé bí ojúṣe tá a ní nínú ìjọ bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ. Ẹ ò rí bó ṣe máa dáa tó táwọn tá a yàn sípò bá ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ. Wọ́n sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá ń gbé ìmọ̀ràn wọn ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í wá bí wọ́n ṣe máa gbayì lójú àwọn ará, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n máa ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (1 Kọ́r. 4:6, 7) Gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni Jèhófà fún lẹ́bùn. A lè ronú pé ojúṣe tá a ní nínú ìjọ ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Bó ti wù kí ojúṣe tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ní kéré tó, gbogbo wa la lè ṣe ipa tiwa láti mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ. Ó ṣe tán, àgbájọ ọwọ́ la fi ń sọ̀yà. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yẹra fún ẹ̀mí ìbánidíje, ká sì pinnu pé àá sa ipá wa láti mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀ nínú ìjọ.—Éfé. 4:3. w21.07 19 ¶18-19
Saturday, February 25
Arákùnrin rẹ máa dìde.—Jòh. 11:23.
Ó dájú pé wàá pa dà rí àwọn èèyàn ẹ tó ti kú. Bí Jésù ṣe sunkún nígbà tó ń tu àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú jẹ́ ẹ̀rí pé ó máa jí àwọn tó ti kú dìde! (Jòh. 11:35) O lè tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú. Kì í ṣe pé Jésù sunkún pẹ̀lú Màtá àti Màríà nìkan ni, ó tún tẹ́tí sí wọn, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. (Jòh. 11:25-27) Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Dan nílẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Nǹkan ò rọrùn fún mi rárá lẹ́yìn tí ìyàwó mi kú. Tọ̀sántòru làwọn tọkọtaya lóríṣiríṣi fi máa ń wà pẹ̀lú mi. Wọ́n máa ń tẹ́tí sí mi, wọ́n sì máa ń tù mí nínú. Wọ́n jẹ́ kí n sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi, tí mo bá sì ń sunkún, wọ́n máa ń fìfẹ́ rẹ̀ mí lẹ́kún. Wọ́n tún máa ń bá mi fọ mọ́tò, wọ́n máa ń bá mi rajà, wọ́n sì máa ń bá mi dáná láwọn àsìkò tí mi ò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń gbàdúrà pẹ̀lú mi. Ṣe ni wọ́n dà bí ọ̀rẹ́ tòótọ́ àti ‘ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.’”—Òwe 17:17. w22.01 16 ¶8-9
Sunday, February 26
Ẹni tó ń fetí sí ìbáwí tó ń fúnni ní ìyè, àárín àwọn ọlọ́gbọ́n ló ń gbé.—Òwe 15:31.
Ohun tó dáa jù ni Jèhófà fẹ́ fún wa. (Òwe 4:20-22) Ó máa ń bá wa wí nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tàbí àwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, ìyẹn ló sì ń fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Héb. 12:9, 10) Ohun tí wọ́n bá ẹ sọ ni kó o wò, má wo bí wọ́n ṣe sọ ọ́. Nígbà míì, tí wọ́n bá gbà wá nímọ̀ràn, ó lè máa ṣe wá bíi pé ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà sọ ọ́ kọ́ nìyẹn. Ká sòótọ́, ó yẹ kẹ́ni tó fẹ́ gba èèyàn nímọ̀ràn sapá láti sọ ọ́ lọ́nà tó máa rọrùn fún ẹni náà láti gbà á. (Gál. 6:1) Tó bá jẹ́ àwa ni wọ́n gbà nímọ̀ràn, ohun tí wọ́n sọ fún wa ló yẹ ká wò, kódà tó bá ń ṣe wá bíi pé ọ̀nà tí wọ́n gbà sọ ọ́ yẹn ò dáa tó. Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Tí inú mi ò bá tiẹ̀ dùn sí ohun tẹ́ni náà sọ fún mi, ṣé òótọ́ ọ̀rọ̀ wà níbẹ̀? Ṣé mo lè gbójú fo àìpé ẹni tó fún mi nímọ̀ràn kí n lè jàǹfààní látinú ohun tó sọ?’ A máa fi hàn pé a gbọ́n tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa. w22.02 12 ¶13-14
Monday, February 27
Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìmọ̀kan di ọlọ́gbọ́n.—Sm. 19:7.
Jèhófà mọ̀ pé ó máa ń gba àkókò àti iṣẹ́ àṣekára ká tó lè borí èròkerò àti ìwà burúkú. (Sm. 103:13, 14) Àmọ́ Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. Àwọn nǹkan yìí ló ń fún wa ní ọgbọ́n, okun àti ìrànwọ́ tó ń mú ká yí ìwà wa pa dà. Máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ ara rẹ wò. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bíi dígí, ó máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ò ń ronú lọ́nà tó tọ́, bóyá ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ dáa àti pé ò ń hùwà tó bá ìlànà Ọlọ́run mu. (Jém. 1:22-25) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà náà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó mọ ọ̀nà tó dáa jù lọ tóun lè gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́, ó sì mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ. (Òwe 14:10; 15:11) Torí náà, bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, kó o sì máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Mọ̀ dájú pé ìlànà Jèhófà ló dára jù. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà ní ká ṣe, a máa jàǹfààní. Àwọn èèyàn máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, ìgbésí ayé wọn máa ń dáa, wọ́n sì máa ń láyọ̀ gan-an.—Sm. 19:8-11. w22.03 4 ¶8-10
Tuesday, February 28
Ẹ kíyè sí àwọn òkìtì tó wà lẹ́yìn ògiri rẹ̀. Ẹ ṣàyẹ̀wò àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò, kí ẹ lè ròyìn rẹ̀ fún ìran ọjọ́ iwájú.—Sm. 48:13.
Tá a bá ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, tá a sì ń tún wọn ṣe, à ń jọ́sìn Jèhófà nìyẹn. Bíbélì sọ pé “iṣẹ́ mímọ́” ni gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn àtàwọn iṣẹ́ ọnà tí wọ́n ṣe sínú ẹ̀. (Ẹ́kís. 36:1, 4) Bákan náà lónìí, tá a bá ń kópa nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ilé ètò Ọlọ́run míì, Jèhófà á kà á sí iṣẹ́ mímọ́. Ọ̀pọ̀ àkókò làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan máa ń lò lẹ́nu iṣẹ́ yìí. A mà mọyì iṣẹ́ ribiribi táwọn ará yìí ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Ìjọba náà o! Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àwọn kan lára wọn tiẹ̀ lè fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àwọn alàgbà náà lè fi hàn pé àwọn ń ti iṣẹ́ ìkọ́lé ètò Ọlọ́run lẹ́yìn. Tí wọ́n bá rí i pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé gba fọ́ọ̀mù aṣáájú-ọ̀nà déédéé, tí wọ́n sì rí i pé wọ́n kúnjú ìwọ̀n, ó yẹ kí wọ́n tètè fọwọ́ sí i. Bóyá akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni wá lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wa pátápátá la lè kó ipa tó jọjú láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa àtàwọn ilé ètò Ọlọ́run míì wà ní mímọ́ tónítóní, kó sì dùn ún wò. w22.03 22 ¶11-12