ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es23 ojú ìwé 26-36
  • March

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • March
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2023
  • Ìsọ̀rí
  • Wednesday, March 1
  • Thursday, March 2
  • Friday, March 3
  • Saturday, March 4
  • Sunday, March 5
  • Monday, March 6
  • Tuesday, March 7
  • Wednesday, March 8
  • Thursday, March 9
  • Friday, March 10
  • Saturday, March 11
  • Sunday, March 12
  • Monday, March 13
  • Tuesday, March 14
  • Wednesday, March 15
  • Thursday, March 16
  • Friday, March 17
  • Saturday, March 18
  • Sunday, March 19
  • Monday, March 20
  • Tuesday, March 21
  • Wednesday, March 22
  • Thursday, March 23
  • Friday, March 24
  • Saturday, March 25
  • Sunday, March 26
  • Monday, March 27
  • Tuesday, March 28
  • Wednesday, March 29
  • Thursday, March 30
  • Friday, March 31
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2023
es23 ojú ìwé 26-36

March

Wednesday, March 1

Torí pé ẹ ti ṣe é fún ọ̀kan lára àwọn arákùnrin mi tó kéré jù lọ yìí, ẹ ti ṣe é fún mi.​—Mát. 25:40.

“Àwọn àgùntàn” inú àkàwé tó wà nínú Mátíù 25:31-36 ṣàpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ èèyàn ní àkókò òpin yìí tí wọ́n nírètí àtigbé ayé, ìyẹn àwọn àgùntàn mìíràn. Wọ́n jẹ́ olóòótọ́, wọ́n sì ń ti àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn ní ti pé, wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ pàtàkì kárí ayé, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Lọ́dọọdún, ọ̀nà míì táwọn àgùntàn mìíràn ń gbà ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn ni pé, láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, wọ́n máa ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé láti pe àwọn tó fìfẹ́ hàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Bákan náà, kárí ayé ni wọ́n ti máa ń rí i dájú pé àwọn ṣe ètò tó yẹ kí wọ́n lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ara àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn nìyẹn, inú wọn sì máa ń dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dá àwọn àgùntàn mìíràn lójú pé Jésù mọ gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe fáwọn ẹni àmì òróró, ó sì mọ̀ pé òun gan-an ni wọ́n ń ṣe é fún.​—Mát. 25:37-40. w22.01 22 ¶11-12

Thursday, March 2

Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.​—Jòh. 14:9.

Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó sì máa ń fàánú hàn sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣàánú adẹ́tẹ̀ kan, ó fìfẹ́ hàn sí obìnrin tó ní àìsàn burúkú kan, ó sì tu àwọn tí èèyàn wọn kú nínú. Táwa náà bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, à ń fara wé Jèhófà nìyẹn. (Máàkù 1:40, 41; 5:25-34; Jòh. 11:33-35) Bá a bá ṣe ń fìwà jọ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa sún mọ́ ọn. Tá a bá ń tọ ipasẹ̀ Jésù, ayé burúkú yìí ò ní pín ọkàn wa níyà. Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ pé: “Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòh. 16:33) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé òun ò jẹ́ kí ayé burúkú yìí àti ohun tí wọ́n ń gbé lárugẹ nípa lórí òun. Jésù ò gbàgbé ìdí tí Jèhófà fi rán an wá sáyé, ìyẹn láti sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Àwa náà ńkọ́? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà nínú ayé tó lè pín ọkàn wa níyà. Àmọ́ bíi ti Jésù, tá a bá pọkàn pọ̀ sórí bá a ṣe máa ṣèfẹ́ Jèhófà, àwa náà máa “ṣẹ́gun” ayé.​—1 Jòh. 5:5. w21.04 3-4 ¶7-8

Friday, March 3

[Kò sóhun tó] máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.​—Róòmù 8:39.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé Jésù ti ṣèlérí pé ‘gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù máa ní ìyè àìnípẹ̀kun.’ (Jòh. 3:16; Róòmù 6:23) Ó sì dájú pé Pọ́ọ̀lù wà lára àwọn tó ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà. Ó dá a lójú pé Jèhófà ṣe tán láti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ títí kan àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tí wọ́n bá ronú pìwà dà. (Sm. 86:5) Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun gan-an. Ó ṣe tán, torí òun ló ṣe rán Kristi wá sáyé kó lè kú fún òun. Ẹ kíyè sí ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó wà ní ìparí Gálátíà 2:20. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run . . . nífẹ̀ẹ́ mi, [ó] sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” Pọ́ọ̀lù ò ronú pé òun ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń nífẹ̀ẹ́ kó wá máa sọ pé, ‘Mo mọ ìdí tí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ àwọn ará yòókù, àmọ́ kò sídìí tó fi máa nífẹ̀ẹ́ èmi.’ Pọ́ọ̀lù rán àwọn ará tó wà ní Róòmù létí pé: “Nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Torí náà, gbogbo wa pátá ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́! Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Pọ́ọ̀lù mọ bí Jèhófà ṣe mú sùúrù gan-an fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. w21.04 22 ¶8-10

Saturday, March 4

Torí ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí nìyí, pé ká pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.​—1 Jòh. 5:3.

Tó o bá ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, rí i pé o ràn án lọ́wọ́ kó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Lọ́nà wo? Máa tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ Jèhófà ní gbogbo ìgbà tẹ́ ẹ bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Jẹ́ kó mọ̀ pé Ọlọ́run aláyọ̀ ni Jèhófà, ó sì máa ń ti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ lẹ́yìn. (1 Tím. 1:11; Héb. 11:6) Jẹ́ kó mọ̀ pé ó máa jàǹfààní tó bá ń fi ohun tó ń kọ́ sílò, ìyẹn sì máa jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Àìsá. 48:17, 18) Bí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á yá a lára láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó lè ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ yááfì àwọn nǹkan kan. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan tara. Àwọn míì máa ní láti fi àwọn ọ̀rẹ́ wọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sílẹ̀. Ní tàwọn míì, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí kò nífẹ̀ẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè pa wọ́n tì. Àmọ́, Jésù ṣèlérí pé àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn òun máa rí ìbùkún gbà. Táwọn mọ̀lẹ́bí wọn bá tiẹ̀ pa wọ́n tì, àwọn ará máa gbárùkù tì wọ́n, wọ́n á sì fìfẹ́ hàn sí wọn.​—Máàkù 10:29, 30. w21.06 4 ¶8-9

Sunday, March 5

Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun, wọ́n ti tó kórè.​—Jòh. 4:35.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn wé iṣẹ́ táwọn àgbẹ̀ máa ń ṣe, tó fi hàn pé iṣẹ́ wa kọjá ká kàn fúnrúgbìn. Ó sọ fún àwọn ará ní Kọ́ríńtì pé: “Èmi gbìn, Àpólò bomi rin . . . Ẹ̀yin jẹ́ pápá Ọlọ́run tí à ń ro lọ́wọ́.” (1 Kọ́r. 3:6-9) Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú “pápá Ọlọ́run,” kì í ṣe pé ká kàn fúnrúgbìn, a tún gbọ́dọ̀ máa bomi rin ín, ká sì máa kíyè sí bó ṣe ń dàgbà. Síbẹ̀, ká máa rántí pé Ọlọ́run ló ń mú kó dàgbà. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa wàásù ká sì máa kọ́ni ní òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! Iṣẹ́ yìí ń fún wa láyọ̀ gan-an. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti dọmọ ẹ̀yìn nílùú Tẹsalóníkà sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀, ó ní: “Kí ni ìrètí tàbí ìdùnnú tàbí adé ayọ̀ wa níwájú Jésù Olúwa wa nígbà tó bá wà níhìn-ín? Ní tòótọ́, ṣé kì í ṣe ẹ̀yin ni? Dájúdájú, ẹ̀yin ni ògo àti ìdùnnú wa.”​—1 Tẹs. 2:19, 20; Ìṣe 17:1-4. w21.07 3 ¶5; 7 ¶17

Monday, March 6

Ẹ rí i pé ẹ ò kẹ́gàn ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí.​—Mát. 18:10.

Bíbélì sọ pé ṣe ni Jèhófà fa ẹnì kọ̀ọ̀kan wa wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀. (Jòh. 6:44) Ẹ ronú ohun tíyẹn túmọ̀ sí. Jèhófà fara balẹ̀ kíyè sí gbogbo èèyàn tó wà láyé, ó sì kíyè sí i pé o lọ́kàn tó dáa àti pé o fẹ́ mọ òun. (1 Kíró. 28:9) Jèhófà mọ̀ ẹ́ dáadáa, ó lóye bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ, ó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ. Ẹ ò rí i pé ìyẹn fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an. Àmọ́ kì í ṣe ìwọ nìkan o, ó tún nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ká lè lóye kókó yìí, Jésù fi Jèhófà wé olùṣọ́ àgùntàn. Tí àgùntàn kan bá sọ nù nínú ọgọ́rùn-ún àgùntàn, kí ni olùṣọ́ àgùntàn kan máa ṣe? Jésù sọ pé ‘ó máa fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ lórí òkè, á sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá èyí tó sọ nù.’ Tí olùṣọ́ àgùntàn náà bá ti rí i, kò ní bínú sí i kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lù ú. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni inú ẹ̀ á dùn. Kí ni ẹ̀kọ́ ibẹ̀? Ẹ̀kọ́ náà ni pé gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan la ṣe pàtàkì sí Jèhófà. Jésù sọ pé: “Kò wu Baba mi tó wà ní ọ̀run pé kí ọ̀kan péré nínú àwọn ẹni kékeré yìí ṣègbé.”​—Mát. 18:12-14. w21.06 20 ¶1-2

Tuesday, March 7

Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run.​—Jém. 4:8.

Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ nípa ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa, ó máa jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àjọṣe àwa àti ẹ̀ á sì túbọ̀ lágbára. (Róòmù 8:38, 39) Ó ń jẹ́ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀. (1 Pét. 2:21) Láwọn ọjọ́ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, a máa ń kà nípa ọ̀sẹ̀ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ikú rẹ̀ àti bó ṣe jíǹde. Tó bá wá di ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀, àsọyé Bíbélì tá a máa ń gbọ́ níbẹ̀ máa ń rán wa létí ìfẹ́ tí Jésù ní sí wa. (Éfé. 5:2; 1 Jòh. 3:16) Torí náà, tá a bá ń kà nípa àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ ní ti bó ṣe kú nítorí wa, tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, ìyẹn á jẹ́ ká lè ‘máa rìn bí Jésù ṣe rìn.’ (1 Jòh. 2:6) Ó ń jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé a máa dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. (Júùdù 20, 21) A máa dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà, tá à ń sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, tá a sì ń múnú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11; Mát. 6:9; 1 Jòh. 5:3) Torí náà, Ìrántí Ikú Kristi tá à ń ṣe máa ń jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa túbọ̀ pinnu pé ‘Títí láé la máa dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run!’ w22.01 23 ¶17; 25 ¶18-19

Wednesday, March 8

Ẹ fúnra yín yan ẹni tí ẹ fẹ́ máa sìn.​—Jóṣ. 24:15.

Jèhófà fún wa lómìnira láti yan ohun tá a fẹ́. A lè pinnu bóyá a máa ṣèfẹ́ Jèhófà àbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá pinnu pé òun la máa sìn. (Sm. 84:11; Òwe 27:11) Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ ìjọsìn, a tún lè pinnu láti ṣe àwọn nǹkan tó dáa. Bíi ti Jésù, àwa náà lè fi ire àwọn míì ṣáájú tiwa. Ìgbà kan wà tó rẹ Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀, wọ́n wá rìnrìn àjò lọ síbì kan tó dá kí wọ́n lè sinmi. Àmọ́ àyè ìyẹn ò yọ fún wọn. Ìdí ni pé nígbà tí wọ́n fi máa dé ibi tí wọ́n ń lọ, wọ́n bá èrò rẹpẹtẹ níbẹ̀, àwọn èrò náà sì fẹ́ kí Jésù kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́. Síbẹ̀, Jésù ò kanra mọ́ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló káàánú wọn. Kí ni Jésù wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ó . . . bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan.” (Máàkù 6:30-34) Bíi ti Jésù, táwa náà bá ń lo àkókò àti okun wa láti ran àwọn míì lọ́wọ́, ṣe là ń fògo fún Jèhófà.​—Mát. 5:14-16. w21.08 3 ¶7-8

Thursday, March 9

Kí kálukú máa . . . láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.​—Gál. 6:4.

Jèhófà ò dá wa pé ká rí bákan náà, ó sì mọyì bá a ṣe yàtọ̀ síra. Ohun tó jẹ́ ká mọ èyí ni pé onírúurú ewéko, ẹranko títí kan èèyàn ni Jèhófà dá. Gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan la sì ní ohun kan tó mú ká yàtọ̀ sáwọn míì. Torí náà, Jèhófà kì í fi wá wéra. Ọkàn wa ni Jèhófà ń wò, ìyẹn ẹni tá a jẹ́ ní inú. (1 Sám. 16:7) Ó mọ ipò àtilẹ̀wá wa, ohun tágbára wa gbé àti ibi tá a kù sí. Bákan náà, kì í béèrè ohun tó ju agbára wa lọ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fara wé Jèhófà, ká máa wo ara wa bí òun náà ṣe ń wò wá. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé a ‘ní àròjinlẹ̀’ ní ti pé a ò ní máa ro ara wa jù tàbí ká máa ro ara wa pin. (Róòmù 12:3) Ká sòótọ́, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, a lè mọ arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Héb. 13:7) A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹ̀, ká sì rí ọ̀nà tá a lè gbà sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Fílí. 3:17) Àmọ́, ìyàtọ̀ wà nínú ká kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnì kan àti ká máa fi ara wa wé ẹni náà. w21.07 20 ¶1-2

Friday, March 10

Ẹ gbé ojú yín sókè ọ̀run, kí ẹ sì wò ó. Ta ló dá àwọn nǹkan yìí?​—Àìsá. 40:26.

Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹranko, ewéko àti ìràwọ̀, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Ẹlẹ́dàá wà. (Sm. 19:1) Bó o bá ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan yìí, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa dá ẹ lójú pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó wà láyìíká ẹ, máa ronú nípa ohun tí wọ́n ń jẹ́ kó o mọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá. (Róòmù 1:20) Bí àpẹẹrẹ, ooru àti ìmọ́lẹ̀ tó ń jáde látinú oòrùn máa ń ṣe wá láǹfààní, àmọ́ ìtànṣán kan tún máa ń jáde lára oòrùn tó lè pa wá lára. Àmọ́, nǹkan kan wà tó máa ń dáàbò bò wá. Kí ni nǹkan náà? Afẹ́fẹ́ kan wà tí wọ́n ń pè ní ozone tí kì í jẹ́ kí ìtànṣán tó ń pani lára yẹn dé ọ̀dọ̀ wa. Bí ìtànṣán tó ń pani lára látinú oòrùn bá ṣe ń lágbára sí i, bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ozone tó ń dáàbò bò wá á ṣe máa pọ̀ sí i. Ṣé o rò pé àwọn nǹkan tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò yìí kàn ṣàdédé wà ni, àbí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ wa tó sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n ló dá wọn? w21.08 17 ¶9-10

Saturday, March 11

Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú. ​—1 Jòh. 4:21.

Lẹ́yìn tẹ́nì kan bá ṣèrìbọmi, ó yẹ ká ṣì máa fìfẹ́ hàn sí i, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún un. (1 Jòh. 4:20) Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká fọkàn tán an. Bí àpẹẹrẹ, a ò ní máa fura òdì sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá máa bọlá fún un, àá sì gbà pé ó sàn jù wá lọ. (Róòmù 12:10; Fílí. 2:3) Ó yẹ ká máa fàánú hàn sí gbogbo èèyàn, ká sì máa ṣoore fún wọn. Tá a bá fẹ́ wà lára ìdílé Ọlọ́run títí láé, ó ṣe pàtàkì pé ká máa fi ìlànà Bíbélì sílò láyé wa. Bí àpẹẹrẹ, Jésù kọ́ wa pé ká máa fàánú hàn sí gbogbo èèyàn títí kan àwọn ọ̀tá wa, ká sì máa ṣoore fún wọn. (Lúùkù 6:32-36) Ìyẹn lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn nígbà míì. Tó bá ṣòro fún ẹ, sapá láti máa ronú, kó o sì máa hùwà bíi ti Jésù. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà tá a sì ń fara wé Jésù, ṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a fẹ́ jẹ́ ara ìdílé ẹ̀ títí láé. w21.08 6 ¶14-15

Sunday, March 12

Ẹ . . . rí i bóyá mi ò ní ṣí ibú omi ọ̀run, kí n sì tú ìbùkún sórí yín. ​—Mál. 3:10.

Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, torí ó ṣèlérí pé òun máa bù kún wa tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé òun tá a sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Nínú Bíbélì, a máa rí àpẹẹrẹ àwọn tí wọ́n lo gbogbo okun wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n ní láti kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ tó fi hàn pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kí Jèhófà tó bù kún wọn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀yìn tí Ábúráhámù fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ ni Jèhófà bù kún un “bí kò tiẹ̀ mọ ibi tó ń lọ.” (Héb. 11:8) Bákan náà, ẹ̀yìn tí Jékọ́bù bá áńgẹ́lì jìjàkadì ló tó rí ìbùkún tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gbà. (Jẹ́n. 32:24-30) Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀yìn táwọn àlùfáà ki ẹsẹ̀ bọ Odò Jọ́dánì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó lè sọdá láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (Jóṣ. 3:14-16) Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lónìí náà ló ti fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tí wọ́n sì ṣe púpọ̀ sí i, a sì lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. w21.08 29-30 ¶12-14

Monday, March 13

Má sọ pé, “Kí nìdí tí àwọn ọjọ́ àtijọ́ fi sàn ju ti ìgbà yìí lọ?”​—Oníw. 7:10.

Ẹ̀yin àgbàlagbà ti rí bí ètò Ọlọ́run ṣe ń ṣe nǹkan láwọn ìgbà kan, síbẹ̀ ẹ múra tán láti ṣàtúnṣe bí nǹkan ṣe ń yí pa dà. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ẹ̀yin àgbàlagbà tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi náà lè kọ́ àwọn míì. Inú àwọn ọ̀dọ́ máa dùn láti gbọ́ àwọn ìrírí yín àtàwọn ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ ti kọ́ nígbèésí ayé yín. Tẹ́ ẹ bá “sọ ọ́ di àṣà láti máa fúnni” láwọn ìrírí tẹ́ ẹ ti ní, ó dájú pé Jèhófà máa bù kún yín gan-an. (Lúùkù 6:38) Tí ẹ̀yin àgbàlagbà bá ń sún mọ́ àwọn ọ̀dọ́, ẹ̀ẹ́ lè ran ara yín lọ́wọ́. (Róòmù 1:12) Kálukú yín ló ní ohun kan tí ẹnì kejì ò ní. Àwọn àgbàlagbà ní ọgbọ́n àti ìrírí, àwọn ọ̀dọ́ sì ní okun àti agbára. Táwọn àgbàlagbà àtàwọn ọ̀dọ́ bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, tí wọ́n sì ṣe ara wọn lọ́kan, ó dájú pé wọ́n á mú ìyìn àti ògo bá Jèhófà Baba wa ọ̀run, wọ́n á sì ṣe gbogbo ìjọ láǹfààní. w21.09 8 ¶3; 13 ¶17-18

Tuesday, March 14

Àwa ń wàásù Kristi tí wọ́n kàn mọ́gi, lójú àwọn Júù, ó jẹ́ ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀.​—1 Kọ́r. 1:23.

Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù fi kọsẹ̀ nítorí ọ̀nà tí wọ́n gbà pa Jésù? Àwọn Júù gbà pé ọ̀daràn àti ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ẹni tí wọ́n bá kàn mọ́gi. Torí náà, wọ́n gbà pé Jésù ò lè jẹ́ Mèsáyà torí pé wọ́n kàn án mọ́gi. (Diu. 21:22, 23) Ṣe làwọn Júù tó kọsẹ̀ torí Jésù kọ̀ láti gbà pé ẹ̀sùn èké ni wọ́n fi kàn án àti pé kò jẹ̀bi. Àwọn tó gbọ́ ẹjọ́ Jésù ò tẹ̀ lé ìlànà ìdájọ́ òdodo rárá àti rárá. Bí àpẹẹrẹ, ìkánjú ni ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn fi kóra jọ láti gbọ́ ẹjọ́ Jésù, wọn ò sì tẹ̀ lé ìlànà ìgbẹ́jọ́. (Lúùkù 22:54; Jòh. 18:24) Dípò káwọn tó gbọ́ ẹjọ́ Jésù fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án àtàwọn ẹ̀rí tí wọ́n mú wá, àwọn adájọ́ yìí fúnra wọn ló ń wá “ẹ̀rí èké tí wọ́n máa fi mú Jésù kí wọ́n lè pa á.” (Mát. 26:59; Máàkù 14:55-64) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, àwọn adájọ́ burúkú yẹn fún àwọn ọmọ ogun Róòmù tó ń ṣọ́ ibojì Jésù ní “ẹyọ fàdákà tó pọ̀” kí wọ́n lè parọ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ló wá jí òkú rẹ̀ gbé.​—Mát. 28:11-15. w21.05 11 ¶12-13

Wednesday, March 15

Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run àti Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àfi Baba nìkan.​—Mát. 24:36.

Jèhófà lágbára láti fòpin sí ayé burúkú yìí nígbàkigbà, àmọ́ dípò bẹ́ẹ̀, ó ń mú sùúrù, sùúrù ẹ̀ sì ń ṣe wá láǹfààní. Aláìpé ni gbogbo àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà nígbà tí wọ́n bí wa. Síbẹ̀, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń bójú tó wa. Jèhófà sì ti ṣèlérí pé òun máa fòpin sí ayé burúkú yìí. (1 Jòh. 4:19) Ó ti ní àsìkò kan lọ́kàn tó máa yanjú gbogbo ìṣòro tó ń bá aráyé fínra. Torí náà, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà yẹ kó mú káwa náà fara dà á títí dìgbà tó máa yanjú gbogbo ìṣòro aráyé. Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó dáa jù tó bá di pé ká fara da nǹkan. Jésù náà sì fìwà jọ Baba rẹ̀ láìkù síbì kan. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fara da ọ̀rọ̀ kòbákùngbé táwọn èèyàn sọ sí i, kò ka ìtìjú sí, ó sì fara da òpó igi oró nítorí wa. (Héb. 12:2, 3) Àpẹẹrẹ Jèhófà ló fún Jésù lókun láti fara dà á, ó sì máa fún ìwọ náà lókun. w21.07 12-13 ¶15-17

Thursday, March 16

Ẹ máa jẹ́ aláàánú, bí Baba yín ṣe jẹ́ aláàánú.​—Lúùkù 6:36.

Ojoojúmọ́ là ń rọ́wọ́ àánú Jèhófà láyé wa. (Sm. 103:10-14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, Jésù fàánú hàn sí wọn, ó sì dárí jì wọ́n. Kódà, ó fẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ ká lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (1 Jòh. 2:1, 2) Ìfẹ́ tó wà láàárín wa máa túbọ̀ jinlẹ̀ tá a bá ń “dárí ji ara [wa] fàlàlà.” (Éfé. 4:32) Nígbà míì, kì í rọrùn láti dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Arábìnrin kan sọ pé àpilẹ̀kọ náà “Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín Fàlàlà” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ ló ran òun lọ́wọ́. Ó ní: “Àpilẹ̀kọ yẹn jẹ́ kí n mọ̀ pé bí ẹnì kan bá ní ẹ̀mí ìdáríjì, kò túmọ̀ sí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń gba ìgbàkugbà láyè tàbí pé ó máa ń fojú kéré bọ́rọ̀ náà ṣe dùn ún tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń gbé ọ̀rọ̀ kúrò lọ́kàn, ìyẹn á sì jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀.” Torí náà, tá a bá ń dárí ji àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní fàlàlà, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, a sì ń fìwà jọ Jèhófà Baba wa ọ̀run. w21.09 23-24 ¶15-16

Friday, March 17

Àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní òtítọ́.​—Jòh. 4:24.

Jésù nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. Ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, ó sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́ yìí. (Jòh. 18:37) Àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ gan-an. (Jòh. 4:23) Kódà, àpọ́sítélì Pétérù pe ẹ̀sìn Kristẹni ní “ọ̀nà òtítọ́.” (2 Pét. 2:2) Nítorí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ gan-an, wọn ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ èké títí kan àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àti àwọn èrò tí ò bá ẹ̀kọ́ òtítọ́ mu. (Kól. 2:8) Bákan náà lónìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ “ń rìn nínú òtítọ́” torí wọ́n ń jẹ́ kí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ọ̀nà ìgbésí ayé wọn bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu láìkù síbì kan. (3 Jòh. 3, 4) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò sọ pé gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì ló yé wa pátápátá. Láwọn ìgbà kan, a ti ṣàṣìṣe nínú ọ̀nà tá a gbà ṣàlàyé Bíbélì àti ọ̀nà tá a gbà ṣètò nǹkan nínú ìjọ. Àmọ́ nígbà tá a bá rí i pé ó yẹ ká ṣàtúnṣe, a máa ń tètè ṣe bẹ́ẹ̀. w21.10 21-22 ¶11-12

Saturday, March 18

Ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ yí ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé E ká.​—Sm. 32:10.

Bí wọ́n ṣe máa ń mọ odi yí ìlú kan ká láyé àtijọ́ láti dáàbò bo àwọn ará ìlú, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa ń fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ yí wa ká, kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó fà wá mọ́ra. (Jer. 31:3) Onísáàmù náà Dáfídì lo àfiwé míì láti fi ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe máa ń dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀. Ó sọ pé: “Ọlọ́run ni ibi ààbò mi, Ọlọ́run tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi.” Dáfídì tún sọ nípa Jèhófà pé: “Òun ni ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ àti ibi ààbò mi, ibi gíga mi tó láàbò àti olùgbàlà mi, apata mi àti Ẹni tí mo fi ṣe ibi ààbò.” (Sm. 59:17; 144:2) Kí nìdí tí Dáfídì ṣe fi ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wé ibi ààbò àti odi ààbò? Ibi yòówù ká máa gbé láyé, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá, ó máa dáàbò bò wá ní gbogbo ọ̀nà kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe tó dáa tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. w21.11 6 ¶14-15

Sunday, March 19

Màá ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ.​—Sm. 77:12.

Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wà lórí òkun tí ìjì líle sì ń jà, Jésù lo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí láti jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára sí i. (Mát. 8:23-26) Nígbà tí ìjì bẹ̀rẹ̀ sí í jà, tí omi sì ń rọ́ wọnú ọkọ̀ náà, ṣe ni Jésù ń sùn. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn wá jí Jésù torí pé ẹ̀rù ti ń bà wọ́n, tí wọ́n sì sọ pé kó gba àwọn, Jésù rọra sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀rù ń bà yín tó báyìí, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?” Ṣé ò ń dojú kọ àwọn ìṣòro tó dà bí “ìjì líle”? Ó lè jẹ́ àjálù kan ló dé bá ẹ. Ó sì lè jẹ́ àìsàn kan ló ń ṣe ẹ́, tó ò sì mọ ohun tó o máa ṣe. Nǹkan lè tojú sú ẹ nígbà míì, àmọ́ má ṣe jẹ́ kíyẹn dí ẹ lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Máa gbàdúrà déédéé kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Máa ronú nípa ìgbà tí Jèhófà ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ sẹ́yìn, ìyẹn máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára. (Sm. 77:11) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀ báyìí, kò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé. w21.11 22 ¶7, 10

Monday, March 20

Ẹ ò gbọ́dọ̀ jalè.​—Léf. 19:11.

Ẹnì kan lè rò pé tóun ò bá ti mú nǹkan tí kì í ṣe tòun, òun ti pa òfin náà mọ́ nìyẹn. Àmọ́, ó lè máa jalè láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, tí oníṣòwò kan bá lo òṣùwọ̀n tí ò péye láti tan àwọn oníbàárà rẹ̀ jẹ, olè ló jà yẹn. Léfítíkù 19:13 jẹ́ ká mọ̀ pé kò sí ìyàtọ̀ nínú kéèyàn jalè àti kéèyàn lu jìbìtì, ó ní: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ lu ọmọnìkejì yín ní jìbìtì.” Torí náà, téèyàn bá lu jìbìtì nínú iṣẹ́ ẹ̀, olè ló jà yẹn, ó sì tún fipá gba nǹkan tí kì í ṣe tiẹ̀. Òfin kẹjọ sọ pé a ò gbọ́dọ̀ jalè, àmọ́ àlàyé tó wà nínú ìwé Léfítíkù ló jẹ́ ká mọ bá a ṣe máa lo ìlànà tó wà nínú òfin náà. Á ṣe wá láǹfààní tá a bá ń ronú lórí ojú tí Jèhófà fi ń wo jìbìtì àti olè jíjà. A lè bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí: ‘Tí mo bá ronú lórí ohun tí Léfítíkù 19:11-13 sọ, ṣé àwọn nǹkan kan wà tí mò ń ṣe tó gba pé kí n ṣàtúnṣe? Ṣé ó yẹ kí n ṣe àtúnṣe kan nínú iṣẹ́ mi tàbí nínú ọ̀nà tí mò ń gbà ṣiṣẹ́?’ w21.12 9-10 ¶6-8

Tuesday, March 21

Bí Jèhófà ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.​—Kól. 3:13.

Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan tó o bá ń gbàdúrà, sọ àwọn nǹkan tó kù díẹ̀ káàtó tó o ṣe fún Jèhófà, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì ẹ́. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo ni, ó máa gba pé kó o sọ fáwọn alàgbà. Wọ́n á tẹ́tí sí ẹ, wọ́n á sì fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á gbàdúrà fún ẹ, wọ́n á sì bẹ Jèhófà pé kó wo ọlá ẹbọ ìràpadà náà mọ́ ẹ lára ‘kó lè mú ẹ lára dá nípa tẹ̀mí.’ (Jém. 5:14-16) Bákan náà, á dáa kó o máa ronú jinlẹ̀ nípa ìràpadà. Ṣé ó máa ń dun ìwọ náà tó o bá ń kà nípa bí wọ́n ṣe fìyà jẹ Jésù gan-an? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, bó o bá ṣe ń ronú jinlẹ̀ nípa ìràpadà tí Jésù ṣe, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tó o ní fún un àti fún Bàbá rẹ̀ ṣe máa jinlẹ̀ sí i. Bá a ṣe ń lọ sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún, tá a sì ń pe àwọn míì wá síbẹ̀ ń mú ká túbọ̀ mọyì ìràpadà. Àbí ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni Jèhófà fún wa láti máa kọ́ àwọn míì nípa Ọmọ rẹ̀! w21.04 18-19 ¶13-16

Wednesday, March 22

Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan.​—Máàkù 6:34.

Ẹ ronú nípa ohun tí Jésù ṣe nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn wá bá a níbi òkè kan. Gbogbo òru ni Jésù fi gbàdúrà. Torí náà, á ti rẹ̀ ẹ́ gan-an. Àmọ́ nígbà tó rí àwọn aláìní àtàwọn tó ń ṣàìsàn, àánú wọn ṣe é. Torí náà, ó wò wọ́n sàn, ṣùgbọ́n kò fi mọ síbẹ̀, ó tún wàásù fún wọn, ó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an. Ìwàásù yẹn la wá mọ̀ sí Ìwàásù orí Òkè. (Lúùkù 6:12-20) Jésù tún lo àkókò tó yẹ kó fi dá wà láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Báwo lẹ ṣe rò pé ó máa rí lára Jésù nígbà tó gbọ́ pé wọ́n ti bẹ́ orí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Jòhánù Onírìbọmi? Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí Jésù gbọ́ [pé wọ́n ti pa Jòhánù], ó wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tó dá, kó lè dá wà.” (Mát. 14:10-13) Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ti débẹ̀ ṣáájú ẹ̀. (Máàkù 6:31-33) Ó rí i pé ó wù wọ́n láti gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé wọ́n nílò ìtùnú, ohun tí Jésù sì ṣe fún wọn gan-an nìyẹn.​—Lúùkù 9:10, 11. w22.02 21 ¶4, 6

Thursday, March 23

Ẹ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn.​—Róòmù 12:18.

Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí i pé a ti ṣẹ ẹnì kan tá a jọ ń sin Jèhófà? Ó yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. A lè ní kó jẹ́ ká yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin wa ní ìtùnbí-ìnùbí. Ó yẹ káwa náà yẹ ara wa wò. A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé mo ṣe tán láti gbà pé mo jẹ̀bi lóòótọ́, kí n sì lọ bẹ ẹni náà kí àlàáfíà lè wà láàárín àwa méjèèjì? Báwo ló ṣe máa rí lára Jèhófà àti Jésù tí wọ́n bá rí i pé mo lọ yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin mi?’ Ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí máa mú ká fetí sí Jésù, ká sì lọ yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹni tá a ṣẹ̀. Tá a bá lọ bá arákùnrin tàbí arábìnrin wa láti yanjú ọ̀rọ̀ kan, ó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀. (Éfé. 4:2, 3) Ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wa ni bí ẹni náà ṣe máa yọ́nú sí wa. Fi sọ́kàn pé bó o ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹni náà ṣe pàtàkì ju kó o máa wá ẹni tó jẹ̀bi tàbí ẹni tó jàre.​—1 Kọ́r. 6:7. w21.12 26 ¶13-16

Friday, March 24

Ó wo ìlú náà, ó sì sunkún lé e lórí.​—Lúùkù 19:41.

Inú Jésù ò dùn torí ó mọ̀ pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù ni ò ní gba ìhìn rere Ìjọba náà. Torí náà, wọ́n máa pa Jerúsálẹ́mù run, àwọn tó bá sì yè bọ́ máa lọ sígbèkùn. (Lúùkù 21:20-24) Ohun tí Jésù sọ gan-an ló ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn ni ò gbà á gbọ́. Ṣé àwọn èèyàn máa ń gbọ́ ìwàásù lágbègbè ibi tóò ń gbé? Tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn ló ń gbọ́, kí lo lè kọ́ látinú bí Jésù ṣe sunkún torí àwọn tó wàásù fún? Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Bí Jésù ṣe sunkún tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an. Bíbélì sọ pé: “Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9) Lónìí, àwa náà lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn tá à ń wàásù fún tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn.​—Mát. 22:39. w22.01 16 ¶10-12

Saturday, March 25

Mo rọ̀ mọ́ ọ; ọwọ́ ọ̀tún rẹ dì mí mú ṣinṣin.​—Sm. 63:8.

Ìgbàgbọ́ ẹ máa lágbára sí i tó o bá ń ronú lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe fáwọn èèyàn ẹ̀ àtohun tó ti ṣe fún ìwọ náà. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á máa pọ̀ sí i. Ìfẹ́ tó ju gbogbo àwọn ànímọ́ yòókù lọ lá jẹ́ kó o máa ṣègbọràn sí Jèhófà, kó o yááfì àwọn nǹkan kan kó o lè múnú rẹ̀ dùn, kó o sì fara da àdánwò èyíkéyìí. (Mát. 22:37-39; 1 Kọ́r. 13:4, 7; 1 Jòh. 5:3) Torí náà, kò sí ohun tó ṣeyebíye ju ìfẹ́ tó wà láàárín àwa àti Jèhófà àti bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀! (Sm. 63:1-7) Rántí pé àdúrà, ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò wà lára ìjọsìn wa. Bíi ti Jésù, wá ibi tó pa rọ́rọ́ tó o bá fẹ́ lo àkókò pẹ̀lú Jèhófà. Yẹra fún ohunkóhun tó lè pín ọkàn ẹ níyà. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè pọkàn pọ̀ nígbà tó o bá ń ṣe ìjọsìn. Torí náà, tó o bá ń lo àkókò ẹ lọ́nà tó dáa ní báyìí, Jèhófà máa jẹ́ kó o gbádùn ayé ẹ títí láé nínú ayé tuntun.​—Máàkù 4:24. w22.01 31 ¶18-20

Sunday, March 26

Ẹ kórìíra ohun búburú.​—Róòmù 12:9.

Nǹkan téèyàn bá ń rò lọ́kàn ló máa ń ṣe. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi kọ́ wa pé ká má gba èròkerò láyè torí ó lè mú ká dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. (Mát. 5:21, 22, 28, 29) A fẹ́ máa múnú Bàbá wa ọ̀run dùn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì ká má gba èròkerò láyè, àmọ́ ojú ẹsẹ̀ ló yẹ ká gbé e kúrò lọ́kàn! Jésù sọ pé: “Ohunkóhun tó bá ń ti ẹnu jáde, inú ọkàn ló ti ń wá.” (Mát. 15:18) Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu wa jáde máa ń sọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. Torí náà, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń sọ òótọ́, kódà tí mo bá mọ̀ pé ó lè kó mi sí ìjàngbọ̀n? Tí mo bá ti ṣègbéyàwó, ṣé mi ò kì í bá ẹlòmíì tage? Ṣé mo máa ń yẹra fún ìsọkúsọ bí mo ṣe máa ń yẹra fún àìsàn tó lè ranni? Ṣé mi ò kì í fìbínú sọ̀rọ̀ tẹ́nì kan bá múnú bí mi?’ Tó o bá ronú dáadáa lórí àwọn ìbéèrè yẹn, á ṣe ẹ́ láǹfààní. Tá a bá mú ọ̀rọ̀ èébú, irọ́ àti ìsọkúsọ kúrò nínú ọ̀rọ̀ wa, á rọrùn fún wa láti bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀. w22.03 5 ¶12-14

Monday, March 27

Ọgbọ́n jẹ́ ti àwọn tó ń wá ìmọ̀ràn.​—Òwe 13:10.

Àwọn tó máa ń gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì sábà máa ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́, tá a bá fi wọ́n wé àwọn tí kì í gbàmọ̀ràn. Torí náà, rí i pé ò ń gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì. Ìgbà wo la lè ní kí àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà gbà wá nímọ̀ràn? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan. (1) Arábìnrin kan ní kí akéde kan tó nírìírí tẹ̀ lé òun lọ sọ́dọ̀ ẹni tóun ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò níbẹ̀, ó ní kí akéde náà gba òun nímọ̀ràn ohun tóun lè ṣe kóun lè túbọ̀ di olùkọ́ tó já fáfá. (2) Nígbà tí arábìnrin kan tí ò tíì lọ́kọ fẹ́ ra aṣọ, ó ní kí arábìnrin míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ bá òun wò ó bóyá aṣọ tóun fẹ́ rà bójú mu. (3) Nígbà tí arákùnrin kan fẹ́ sọ àsọyé nígbà àkọ́kọ́, ó sọ fún arákùnrin kan tó ti ń sọ àsọyé tipẹ́ pé kó máa fọkàn bá òun lọ bóun ṣe ń sọ àsọyé náà. Ó sì ní kó sọ àwọn ibi tó yẹ kóun ti ṣàtúnṣe kóun lè tẹ̀ síwájú. Kódà, arákùnrin kan tó ti ń sọ àsọyé fún ọ̀pọ̀ ọdún lè lọ bá arákùnrin míì tóun náà ti ń sọ àsọyé tipẹ́ pé kó sọ àwọn ibi tó yẹ kóun ti ṣàtúnṣe nínú àsọyé tóun sọ, kó sì rí i pé òun ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn tí arákùnrin náà bá fún òun. Òwe 19:20. w22.02 13 ¶15-17

Tuesday, March 28

Mi ò dá wà, àmọ́ Baba tó rán mi wà pẹ̀lú mi.​—Jòh. 8:16.

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń bójú tó wa, bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Jésù tó sì bójú tó o nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Jòh. 5:20) Ó pèsè gbogbo ohun tí Jésù nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí, ó sì tún fún un lókun nígbà tó ní ìdààmú ọkàn. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà sọ fún Jésù pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, òun sì ti tẹ́wọ́ gbà á. (Mát. 3:16, 17) Ó dá Jésù lójú pé Bàbá òun nífẹ̀ẹ́ òun àti pé kò ní fi òun sílẹ̀ nígbàkigbà. Bíi ti Jésù, gbogbo wa la ti rí bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa lónírúurú ọ̀nà. Rò ó wò ná: Jèhófà jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ òun, ó sì jẹ́ ká wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé tó nífẹ̀ẹ́ wa. Wọ́n máa ń múnú wa dùn, wọ́n sì máa ń fún wa lókun tá a bá rẹ̀wẹ̀sì. (Jòh. 6:44) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa déédéé. Ó sì máa ń pèsè jíjẹ àti mímu fún wa lójoojúmọ́. (Mát. 6:31, 32) Tá a bá ń ronú nípa ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. w21.09 22 ¶8-9

Wednesday, March 29

Ẹ bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀.​—Kól. 3:9.

Báwo ni ìgbésí ayé ẹ ṣe rí kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ọ̀pọ̀ wa ni ò ní fẹ́ rántí ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe nínú ayé làwa náà ń bá wọn ṣe. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ wa ṣe rí nìyẹn, á jẹ́ pé ‘a ò nírètí, a ò sì ní Ọlọ́run nínú ayé’ wa nígbà yẹn. (Éfé. 2:12) Àmọ́, lẹ́yìn tó o bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o wá rí i pé o ní Bàbá kan tó wà lọ́run, ó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, o rí i pé tó o bá fẹ́ ṣèfẹ́ Jèhófà, tó o sì fẹ́ di ara àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀, o gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà ńlá kan nígbèésí ayé ẹ, àwọn ìlànà Jèhófà lo sì gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. (Éfé. 5:3-5) Jèhófà ló dá wa, òun sì ni Bàbá wa. Torí náà, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ bó ṣe yẹ kí àwa ọmọ ẹ̀ máa hùwà. Ohun tó fẹ́ ni pé ká ti “bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀” ká tó ṣèrìbọmi. w22.03 2 ¶1-3

Thursday, March 30

Mo ní àwọn àgùntàn mìíràn.​—Jòh. 10:16.

Inú àwọn àgùntàn mìíràn máa ń dùn tí wọ́n bá wà níbi Ìrántí Ikú Kristi, tí wọ́n sì ń ronú nípa ìrètí tí wọ́n ní. Wọ́n máa ń fẹ́ gbọ́ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi torí àsọyé náà sábà máa ń dá lórí ohun tí Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa bá a ṣàkóso máa ṣe fún àwọn olóòótọ́ èèyàn nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀. Nígbà tí Jésù Kristi Ọba bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, òun àtàwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ máa sọ ayé di Párádísè, wọ́n sì máa ran àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn lọ́wọ́ láti di ẹni pípé. Ẹ wo bí inú ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tó máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi ṣe máa dùn tó bí wọ́n ṣe ń fojú inú wo ìgbà táwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì máa ṣẹ, irú bí Àìsáyà 35:5, 6; 65:21-23; àti Ìfihàn 21:3, 4. Bí wọ́n ṣe ń fojú inú wo ara wọn àtàwọn èèyàn wọn nínú ayé tuntun, ìyẹn ń jẹ́ kó túbọ̀ dá wọn lójú pé àwọn máa gbé ayé lọ́jọ́ iwájú. Ó sì ń jẹ́ kí wọ́n máa sin Jèhófà nìṣó láìyẹsẹ̀.​—Mát. 24:13; Gál. 6:9. w22.01 21 ¶5-7

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 9) Mátíù 26:6-13

Friday, March 31

Ọmọ èèyàn wá kó lè fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.​—Máàkù 10:45.

Kí ni ìràpadà? Ìràpadà lohun tí Jésù san láti dá wa nídè lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (1 Kọ́r. 15:22) Kí nìdí tá a fi nílò ìràpadà? Ìdí ni pé nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí ohunkóhun bá la ẹ̀mí lọ, Jèhófà sọ pé kí wọ́n fi ẹ̀mí dípò ẹ̀mí. (Ẹ́kís. 21:23, 24) Ìwàláàyè pípé ni Ádámù gbé sọ nù nígbà tó ṣẹ̀. Torí náà, ó pọn dandan kí Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé lélẹ̀ kó lè mú ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣẹ. (Róòmù 5:17) Ó wá tipa bẹ́ẹ̀ di “Baba Ayérayé” fún gbogbo àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ìràpadà. (Àìsá. 9:6; Róòmù 3:23, 24) Jésù fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ torí ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà àti fún wa. (Jòh. 14:31; 15:13) Ìfẹ́ tó ní yìí ló mú kó jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú kó lè mú ìfẹ́ Baba rẹ̀ ṣẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún àwa èèyàn àti ilẹ̀ ayé máa ṣẹ. w21.04 14 ¶2-3

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 9) Mátíù 21:1-11, 14-17

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́