April
Saturday, April 1
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni.—Jòh. 3:16.
Jésù fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa torí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. (Jòh. 15:13) Kò sóhun tá a lè ṣe láti san oore tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa yìí pa dà. Àmọ́ a lè fi hàn pé a mọrírì ohun tí wọ́n ṣe tá a bá ń ronú lórí ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa ojoojúmọ́. (Kól. 3:15) Àwọn ẹni àmì òróró mọyì ìràpadà torí pé òun ló jẹ́ kí wọ́n nírètí àtigbé lọ́run. (Mát. 20:28) Nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, Jèhófà pè wọ́n ní olódodo, ó sì sọ wọ́n dọmọ rẹ̀. (Róòmù 5:1; 8:15-17, 23) Àwọn àgùntàn mìíràn náà fi hàn pé àwọn mọrírì ìràpadà. Torí pé àwọn náà nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, ó jẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, ó ń jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n nírètí pé ‘àwọn máa la ìpọ́njú ńlá já.’ (Ìfi. 7:13-15) Torí náà, ọ̀nà kan táwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn ń gbà fi hàn pé àwọn mọyì ìràpadà ni pé wọ́n máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún. w22.01 23 ¶14-15
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 10) Mátíù 21:18, 19; 21:12, 13; Jòhánù 12:20-50
Sunday, April 2
Kristi rà wá.—Gál. 3:13.
Ohun tó ká Jésù lára jù ni ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run. (Mát. 26:64-66) Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án yìí dùn ún débi pé ó bẹ Jèhófà pé kó má jẹ́ kóun kú lọ́nà tó máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Rẹ̀. (Mát. 26:38, 39, 42) Wọ́n ní láti gbé Jésù kọ́ sórí òpó igi kó lè gba àwọn Júù sílẹ̀ lọ́wọ́ ègún tó wà lórí wọn. (Gál. 3:10) Kí nìdí táwọn Júù fi dẹni ègún? Ìdí ni pé wọ́n ṣèlérí pé àwọn máa pa Òfin Ọlọ́run mọ́, àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, ègún yìí jẹ́ àfikún sí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí wọ́n jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. (Róòmù 5:12) Òfin Ọlọ́run sọ pé tí ẹnì kan bá dẹ́ṣẹ̀ tó yẹ fún ikú, kí wọ́n pa á. Lẹ́yìn náà, wọ́n lè gbé òkú rẹ̀ kọ́ sórí òpó igi. (Diu. 21:22, 23; 27:26) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ Jésù, bí wọ́n ṣe gbé Jésù kọ́ sórí òpó igi mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti bọ́ lọ́wọ́ ègún tó wà lórí wọn, kí wọ́n sì jàǹfààní látinú ìràpadà náà. w21.04 16 ¶5-6
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 11) Mátíù 21:33-41; 22:15-22; 23:1-12; 24:1-3
Monday, April 3
Mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀.—Jòh. 10:17.
Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù lọ́jọ́ tó lò kẹ́yìn láyé. Àwọn ọmọ ogun Róòmù fìyà jẹ ẹ́ bí ẹni máa kú. (Mát. 26:52-54; Jòh. 18:3; 19:1) Wọ́n fi kòbókò tó ní egungun nà án, ìyẹn sì fa ẹran ara ẹ̀ ya. Nígbà tó yá, wọ́n mú kó wọ́ igi ńlá kan pẹ̀lú ẹ̀yìn tó ti bó yánnayànna. Jésù gbìyànjú láti wọ́ igi náà lọ síbi tí wọ́n ti máa pa á, àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn, àwọn ọmọ ogun Róòmù fipá mú ọkùnrin kan láti bá a gbé igi náà. (Mát. 27:32) Nígbà tí Jésù dé ibi tí wọ́n ti máa pa á, àwọn ọmọ ogun yẹn kan ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ mọ́ òpó náà. Nígbà tí wọ́n gbé òpó yẹn nà ró, ṣe ni ojú ọgbẹ́ tí wọ́n fi ìṣó kàn náà ya. Ìyá ẹ̀ ń sunkún, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, àmọ́ ńṣe làwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́. (Lúùkù 23:32-38; Jòh. 19:25) Odindi wákàtí mẹ́ta ni Jésù fi joró lórí òpó igi oró yìí, ó le débi pé agbára káká ló fi ń mí. Nígbà tó ku díẹ̀ kó kú, ó gba àdúrà ìkẹyìn, lẹ́yìn náà, ó dorí kodò, ó sì kú. (Máàkù 15:37; Lúùkù 23:46; Jòh. 10:18; 19:30) Ẹ ò rí i pé ikú oró, ikú ẹ̀sín ni Jésù kú! w21.04 16 ¶4
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 12) Mátíù 26:1-5, 14-16; Lúùkù 22:1-6
ỌJỌ́ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
Lẹ́yìn Tí Oòrùn Bá Wọ̀
Tuesday, April 4
Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.—Lúùkù 22:19.
Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ mọ́kànlá (11) nípa májẹ̀mú méjì, ìyẹn májẹ̀mú tuntun àti májẹ̀mú Ìjọba. (Lúùkù 22:20, 28-30) Májẹ̀mú méjì yìí ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn àpọ́sítélì àtàwọn èèyàn kéréje míì láti di ọba àti àlùfáà ní ọ̀run. (Ìfi. 5:10; 14:1) Kìkì àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró tí májẹ̀mú méjì náà wà fún, ló máa jẹ búrẹ́dì, tí wọ́n sì máa mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi. Ìrètí tí Jèhófà fún wọn yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé wọ́n máa gba àìleèkú àti àìdíbàjẹ́ ní ọ̀run. Àwọn àti ìyókù àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó ti wà lọ́run máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù Kristi tá a ti ṣe lógo. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wọ́n máa láǹfààní láti rí Jèhófà Ọlọ́run! (1 Kọ́r. 15:51-53; 1 Jòh. 3:2) Àwọn ẹni àmì òróró mọ̀ pé àwọn gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú.—2 Tím. 4:7, 8. w22.01 21 ¶4-5
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 13) Mátíù 26:17-19; Lúùkù 22:7-13 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 14) Mátíù 26:20-56
Wednesday, April 5
O máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.—Lúùkù 23:43.
Wọ́n kan àwọn ọ̀daràn méjì mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù. (Lúùkù 23:40, 41) Ọ̀kan lára wọn yíjú sí Jésù, ó sì sọ pé: “Rántí mi tí o bá dé inú Ìjọba rẹ.” (Lúùkù 23:42) Jésù ṣe ìlérí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ fún ọkùnrin yìí torí ó mọ̀ pé aláàánú ni Jèhófà. (Sm. 103:8; Héb. 1:3) Ó máa ń wu Jèhófà láti fàánú hàn sí wa, kó sì dárí jì wá. Àmọ́ kí Jèhófà tó lè dárí jì wá, a gbọ́dọ̀ kábàámọ̀ ohun tá a ṣe ká sì nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. (1 Jòh. 1:7) Ó máa ń ṣe àwọn kan bíi pé Jèhófà ò lè dárí jì wọ́n láé. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn, rántí pé Jésù fàánú hàn sí ọ̀daràn kan tó bẹ̀rẹ̀ sí í nígbàgbọ́ nígbà tó ku díẹ̀ kó kú. Tí irú ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ bá lè rí àánú gbà, ó dájú pé Jèhófà máa fàánú hàn sáwa ìránṣẹ́ rẹ̀!—Sm. 51:1; 1 Jòh. 2:1, 2. w21.04 9 ¶5-6
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 14) Mátíù 27:1, 2, 27-37
Thursday, April 6
Jésù sọ pé: “A ti ṣe é parí!”—Jòh. 19:30.
Jésù ṣàṣeparí àwọn nǹkan kan bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú. Lákọ̀ọ́kọ́, Jésù fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé èèyàn pípé lè jẹ́ olóòótọ́ láìka ohun yòówù kí Sátánì ṣe fún un. Ìkejì, Jésù fi ẹ̀mí ẹ̀ ṣe ìràpadà. Bó ṣe fẹ̀mí ẹ̀ rà wá pa dà mú kó ṣeé ṣe fáwa èèyàn aláìpé láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, ká sì nírètí àtiwà láàyè títí láé lọ́jọ́ iwájú. Ìkẹta, Jésù fi hàn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, ó sì mú gbogbo ẹ̀gàn tí wọ́n mú bá orúkọ Bàbá rẹ̀ kúrò. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bíi pé ọjọ́ kan tó kù fún wa nìyẹn láti jẹ́ adúróṣinṣin! Tí ikú bá sì dé, ọkàn wa á balẹ̀ láti sọ pé “Jèhófà, mo ti ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti jẹ́ olóòótọ́, mo ti fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, mo ti sọ orúkọ rẹ di mímọ́, mo sì ti fi hàn pé ìwọ ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run!” w21.04 12 ¶13-14
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 15) Mátíù 27:62-66 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 16) Mátíù 28:2-4
Friday, April 7
Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà. Ẹ fetí sí i.—Mát. 17:5.
Wọ́n fẹ̀sùn èké kan Jésù, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́ pé ó jẹ̀bi ohun tí ò ṣe. Lẹ́yìn náà, wọ́n fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n fìyà jẹ ẹ́, wọ́n tún kàn án mọ́ òpó igi oró, kó lè jẹ̀rora títí táá fi kú. Ẹ wo bí ìrora Jésù ṣe máa pọ̀ tó bí wọ́n ṣe ń gbá ìṣó mọ́ ọn ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀, ó dájú pé ara á máa ni ín bó ṣe ń mí, tó sì ń sọ̀rọ̀. Láìka ìrora yẹn sí, àwọn nǹkan pàtàkì kan wà tí Jésù gbọ́dọ̀ sọ. Ó dájú pé àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kẹ́yìn! A ti rí i pé ó yẹ ká máa dárí ji àwọn míì, kó sì dá àwa náà lójú pé Jèhófà máa dárí jì wá. Bákan náà, a ní àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó yí wa ká, tí wọ́n sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nílò ìrànlọ́wọ́ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, a mọ̀ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò èyíkéyìí tó bá dé bá wa. A sì rí ìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa máa lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bíi pé ọjọ́ kan tó kù fún wa nìyẹn láti jẹ́ adúróṣinṣin torí ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé wa. w21.04 8 ¶1; 13 ¶17
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 16) Mátíù 28:1, 5-15
Saturday, April 8
Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.—Jòh. 17:3.
Tá a bá ń tọ ipasẹ̀ Jésù, a máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ kan bi Jésù pé kí ni kóun ṣe kóun lè ní ìyè àìnípẹ̀kun, Jésù dá a lóhùn pé: “Wá máa tẹ̀ lé mi.” (Mát. 19:16-21) Jésù sọ fáwọn Júù tí ò gbà pé òun ni Kristi pé: ‘Àwọn àgùntàn mi ń tẹ̀ lé mi. Mo sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.’ (Jòh. 10:24-29) A lè fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Jésù tá a bá ń fi ohun tó kọ́ni sílò, tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní kúrò lójú ọ̀nà tó lọ síyè àìnípẹ̀kun. (Mát. 7:14) Ká tó lè máa tọ ipasẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí, a gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n dáadáa. A ò lè fi ọjọ́ kan ṣoṣo “mọ” Jésù, ohun tí àá máa ṣe títí lọ ni. A gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ ẹ̀, bó ṣe ń ronú àtàwọn ìlànà ẹ̀. Bó ti wù ká pẹ́ tó nínú òtítọ́, a ṣì gbọ́dọ̀ sapá láti máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀. w21.04 4 ¶9-10
Sunday, April 9
Asọ̀rọ̀ òdì ni mí tẹ́lẹ̀, mo máa ń ṣe inúnibíni.—1 Tím. 1:13.
Ó dájú pé àwọn ìgbà kan máa wà táá máa dun àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó bá ń rántí àwọn nǹkan tó ti ṣe sẹ́yìn. Ó ka ara ẹ̀ sí “àkọ́kọ́ lára” àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ìyẹn ò sì yani lẹ́nu. (1 Tím. 1:15) Kí Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, ó máa ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni láti ìlú kan sí òmíì. Ó fi àwọn kan sẹ́wọ̀n, ó sì fọwọ́ sí bí wọ́n ṣe pa àwọn míì. (Ìṣe 26:10, 11) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Pọ́ọ̀lù tó bá pàdé Kristẹni kan tó sì jẹ́ pé òun ló fọwọ́ sí bí wọ́n ṣe pa àwọn òbí ẹ̀. Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù kábàámọ̀ àwọn nǹkan tó ṣe sẹ́yìn, àmọ́ ó mọ̀ pé kò sí ohun tóun lè ṣe nípa ẹ̀. Ó gbà pé òun ni Kristi kú fún, ó sì sọ pé: “Nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́.” (1 Kọ́r. 15:3, 10) Kí lèyí kọ́ wa? Gbà pé torí ẹ ni Jésù ṣe kú kó o lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. (Ìṣe 3:19) Kì í ṣe àwọn àṣìṣe tá a ṣe sẹ́yìn ni Jèhófà ń wò, ohun tó ṣe pàtàkì sí i ni ohun tá à ń ṣe báyìí àtèyí tá a máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.—Àìsá. 1:18. w21.04 23 ¶11
Monday, April 10
Ẹ dán àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí wò kí ẹ lè mọ̀ bóyá ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá, torí ọ̀pọ̀ wòlíì èké ló ti jáde lọ sínú ayé.—1 Jòh. 4:1.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù nígbà ayé Jésù ò retí pé Mèsáyà máa kú, ẹ kíyè sí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí Mèsáyà. Ó ní: “Ó tú ẹ̀mí rẹ̀ jáde, àní títí dé ikú, wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀; ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bẹ̀bẹ̀.” (Àìsá. 53:12) Torí náà, kò sídìí tó fi yẹ káwọn Júù kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn èké kan Jésù tí wọ́n sì pa á. Ohun kan tá a lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀ ni pé ká máa ṣèwádìí dáadáa ká lè mọ ohun tó jẹ́ òótọ́. Nínú Ìwàásù orí Òkè, Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé wọ́n máa “parọ́ oríṣiríṣi ohun burúkú mọ́” wọn. (Mát. 5:11) Sátánì ló wà lẹ́yìn àwọn irọ́ yẹn, òun ló mú káwọn alátakò máa parọ́ mọ́ àwa tá a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. (Ìfi. 12:9, 10) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n fi àwọn irọ́ yẹn tàn wá jẹ. Ká má sì jẹ́ kí wọ́n fi àwọn irọ́ yẹn kó wa láyà jẹ tàbí jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀. w21.05 11 ¶14; 12 ¶16
Tuesday, April 11
Ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.—Mát. 10:31.
Ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ lọ́wọ́ kó lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Jésù fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lójú pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. (Mát. 10:19, 20, 29, 30) Fi dá akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lójú pé Jèhófà máa ran òun náà lọ́wọ́. O lè ràn án lọ́wọ́ láti gbára lé Jèhófà tó o bá ń fi àfojúsùn rẹ̀ sínú àdúrà tẹ́ ẹ̀ ń gbà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Franciszek tó ń gbé ní Poland sọ pé: “Ẹni tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ sábà máa ń mẹ́nu ba àwọn àfojúsùn mi nínú àdúrà. Bí mo ṣe rí i tí Jèhófà ń dáhùn àdúrà ẹni tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà. Mo rí i pé Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbà tí mo ní kí wọ́n fún mi láyè lẹ́nu iṣẹ́ kí n lè máa lọ sípàdé àti àpéjọ agbègbè.” Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa gan-an. Jèhófà mọ̀ pé iṣẹ́ ńlá là ń ṣe bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ òun, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Àìsá. 52:7) Ká tiẹ̀ wá sọ pé o ò lẹ́ni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí, tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn akéde míì lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn, wàá láyọ̀ pé ìwọ náà ń ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n á fi ṣèrìbọmi. w21.06 7 ¶17-18
Wednesday, April 12
Òfin Jèhófà máa ń mú inú rẹ̀ dùn, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru.—Sm. 1:2.
A lè fi hàn pé a mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a bá ń kà á déédéé. Ó yẹ ká ní ètò tó ṣe gúnmọ́ tó bá di pé ká máa dá kẹ́kọ̀ọ́, kì í ṣe ká kàn máa ṣe é ní ìdákúrekú. Tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, ìgbàgbọ́ wa ò ní jó rẹ̀yìn. A yàtọ̀ pátápátá sí “àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye” ayé yìí, ìdí sì ni pé ìgbàgbọ́ wa fẹsẹ̀ múlẹ̀ torí àwọn ẹ̀rí tó dájú tá a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mát. 11:25, 26) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jẹ́ ká mọ ìdí tí wàhálà fi pọ̀ láyé àtohun tí Jèhófà máa ṣe sí i. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i, àá sì ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. (1 Tím. 2:3, 4) Bákan náà, ẹ jẹ́ ká máa fojú sọ́nà fún ìgbà tí gbogbo àwọn tó wà láyé á panu pọ̀ láti yin Jèhófà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìfihàn 4:11 pé: “Jèhófà, Ọlọ́run wa, ìwọ ló tọ́ sí láti gba ògo . . . torí ìwọ lo dá ohun gbogbo.” w21.08 19 ¶18-20
Thursday, April 13
Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín.—Róòmù 12:10.
Torí pé àwọn alàgbà ló ń bójú tó àwọn ará nínú ìjọ, àwọn ló yẹ kó máa fún àwọn ará nímọ̀ràn nígbà tó bá yẹ. Àfi kí wọ́n sapá kí wọ́n lè máa gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn lọ́nà tó máa ṣe wọ́n láǹfààní, tó máa jẹ́ kí wọ́n gba ìmọ̀ràn náà, tó sì ‘máa mú ọkàn wọn yọ̀.’ (Òwe 27:9) Àwọn alàgbà nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ. Àmọ́ nígbà míì, ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ẹnì kan tó fẹ́ ṣi ẹsẹ̀ gbé ló máa fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Gál. 6:1) Àmọ́ kí alàgbà kan tó lọ gba ẹnì kan nímọ̀ràn, ó yẹ kó ronú lórí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìfẹ́. Ó ní: “Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù àti inú rere. . . . Ó máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra, ó máa ń gba ohun gbogbo gbọ́, ó máa ń retí ohun gbogbo, ó máa ń fara da ohun gbogbo.” (1 Kọ́r. 13:4, 7) Tó bá ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, ó máa jẹ́ kó mọ ìdí tí òun fi fẹ́ lọ gba ẹni náà nímọ̀ràn àti bóun ṣe lè ṣe é lọ́nà tó máa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Tí ẹni tí wọ́n fẹ́ gbà nímọ̀ràn bá rí i pé alàgbà náà nífẹ̀ẹ́ òun, ó máa rọrùn fún un láti gba ìmọ̀ràn náà. w22.02 14 ¶3; 15 ¶5
Friday, April 14
Wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i, wọ́n sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.—Àìsá. 63:10.
Jèhófà dá àwa ọmọ ẹ̀, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn lọ́nà tó pé. Àmọ́, Sátánì tó túmọ̀ sí “Alátakò” ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ó sì mú kí Ádámù àti Éfà náà kẹ̀yìn sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, àwọn áńgẹ́lì àtàwọn èèyàn míì náà ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. (Júùdù 6) Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn dun Jèhófà gan-an. Síbẹ̀, Jèhófà fara dà á. Á sì máa fara dà á títí dìgbà tí àkókò á tó láti pa gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run. Tó bá dìgbà yẹn, inú Jèhófà àtàwọn olóòótọ́ máa dùn pé kò sí àwọn ẹni ibi mọ́! Sátánì fẹ̀sùn kan Jóòbù pé torí ohun tó ń rí gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run ló ṣe ń sìn ín, ẹ̀sùn yẹn sì kan gbogbo àwa tá à ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà. (Jóòbù 1:8-11; 2:3-5) Èṣù ṣì ń fẹ̀sùn kan àwa ìránṣẹ́ Jèhófà títí dòní olónìí. (Ìfi. 12:10) A lè fi hàn pé irọ́ lèṣù ń pa tá a bá ń fara da àwọn ìṣòro wa, tá a sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà torí pé a nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀. w21.07 9 ¶7-8
Saturday, April 15
Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi; ẹ jáwọ́ nínú ìwà burúkú.—Àìsá. 1:16.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo àfiwé kan tó wọni lọ́kàn tó jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká yí ìwà wa pa dà. Ó sọ pé a gbọ́dọ̀ kan ìwà wa àtijọ́ “mọ́gi.” (Róòmù 6:6) Ohun tó ń sọ ni pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi. Tá a bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Jèhófà bí Jésù ti ṣe, ó yẹ ká jáwọ́ nínú gbogbo ìwà burúkú tí Jèhófà kórìíra. Ó dìgbà tá a bá ṣe àwọn nǹkan yìí ká tó ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ká sì láǹfààní láti wà láàyè títí láé. (Jòh. 17:3; 1 Pét. 3:21) Jèhófà ò ní yí àwọn ìlànà ẹ̀ pa dà kó lè múnú wa dùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa ló yẹ ká yí ìwà wa pa dà ká lè máa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. (Àìsá. 1:17, 18; 55:9) Lẹ́yìn tó o bá ti ṣèrìbọmi, ó yẹ kó o ṣì máa gbógun ti èròkerò. Gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́, gbára lé ẹ̀mí rẹ̀, má ṣe gbára lé okun rẹ. (Gál. 5:22; Fílí. 4:6) A gbọ́dọ̀ pinnu pé a máa bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, a ò sì ní gbé e wọ̀ mọ́. w22.03 6 ¶15-17
Sunday, April 16
Jèhófà yóò gbé ọ ró. —Sm. 55:22.
Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò bí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé tá a bá fi Ìjọba rẹ̀ sípò àkọ́kọ́, tá a sì ń fi ìlànà rẹ̀ sílò. (Mát. 6:33) Tá a bá fìyẹn sọ́kàn, a ò ní máa ronú pé àwọn nǹkan tara tó wà láyé yìí ló máa fún wa láyọ̀, táá sì fi wá lọ́kàn balẹ̀. A mọ̀ pé ohun kan ṣoṣo tó lè fún wa ní ìbàlẹ̀ ọkàn ni pé ká máa ṣèfẹ́ Jèhófà. (Fílí. 4:6, 7) Kódà tá a bá tiẹ̀ lówó láti ra ọ̀pọ̀ nǹkan, ó yẹ ká bi ara wa pé ṣé a nílò wọn lóòótọ́, ṣé a sì máa ráyè bójú tó wọn? Ṣé ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan yẹn gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ? Ẹ rántí pé Jèhófà fẹ́ kọ́wọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ tó gbé fún wa. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí nǹkan míì dí wa lọ́wọ́ iṣẹ́ náà. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ dà bí ọ́kùnrin tí Jésù fún láǹfààní láti di ọmọlẹ́yìn òun kó sì di ara ìdílé Jèhófà, àmọ́ tó kọ̀ nítorí àwọn nǹkan tí kò tó nǹkan tó kó jọ!—Máàkù 10:17-22. w21.08 6 ¶17
Monday, April 17
Ẹ gbèjà ara yín níwájú gbogbo èèyàn.—1 Pét. 3:15.
Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá túbọ̀ mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àtàwọn ànímọ́ tó ní, àwọn ànímọ́ yìí sì ṣe kedere nínú àwọn nǹkan tó dá. Àwọn nǹkan tó o kọ́ yìí máa jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà wà lóòótọ́. (Ẹ́kís. 34:6, 7; Sm. 145:8, 9) Bó o ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà, ìgbàgbọ́ rẹ á túbọ̀ máa lágbára, ìfẹ́ tó o ní fún un á túbọ̀ jinlẹ̀, ìyẹn á sì jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn. Máa sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì. Àmọ́ tẹ́nì kan tó o wàásù fún ò bá gbà pé Ọlọ́run wà, tí o ò sì mọ ohun tó o máa sọ, kí ló yẹ kó o ṣe? O lè ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, kó o sì ṣàlàyé ẹ̀ fún ẹni náà. O tún lè ní kí Ẹlẹ́rìí kan tó nírìírí ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bóyá ẹni tó o wàásù fún náà gba àlàyé tó o ṣe látinú Bíbélì tàbí kò gbà á, ìwádìí tó o ti ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, ìgbàgbọ́ rẹ á sì túbọ̀ lágbára. w21.08 18 ¶14-15
Tuesday, April 18
Mi ò fà sẹ́yìn nínú sísọ fún yín.—Ìṣe 20:20.
Kò dìgbà tá a bá yááfì gbogbo ohun tá à ń gbádùn ká tó lè múnú Jèhófà dùn. (Oníw. 5:19, 20) Àmọ́ tá ò bá ṣe púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà torí pé ó nira fún wa láti yááfì àwọn nǹkan tá à ń gbádùn, ṣe lọ̀rọ̀ wa máa dà bí ọkùnrin tí Jésù ṣàkàwé ẹ̀ pé bó ṣe máa gbádùn ayé ẹ̀ ló gbà á lọ́kàn dípò bó ṣe máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. (Lúùkù 12:16-21) Tá a bá kojú ìṣòro, ó yẹ ká gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, ká sì ronú nípa ohun tá a lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà. (Òwe 3:21) Ọ̀pọ̀ nǹkan rere ni Jèhófà ti ṣe fún wa. A lè fi hàn pé a mọyì àwọn nǹkan rere yìí tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fògo fún Jèhófà. (Héb. 13:15) A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ìyẹn sì máa mú kí Jèhófà bù kún wa lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Lójoojúmọ́, ẹ jẹ́ ká máa wá ọ̀nà tá a lè gbà ‘tọ́ Jèhófà wò, ká sì rí i pé ẹni rere ni.’ (Sm. 34:8) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lọ̀rọ̀ wa máa dà bíi ti Jésù tó sọ pé: “Oúnjẹ mi ni pé kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi, kí n sì parí iṣẹ́ rẹ̀.”—Jòh. 4:34. w21.08 30-31 ¶16-19
Wednesday, April 19
Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun, ẹ̀mí ìgbéraga ló sì ń ṣáájú ìkọ̀sẹ̀.—Òwe 16:18.
Sátánì fẹ́ ká máa gbéra ga. Ó mọ̀ pé tá a bá jẹ́ kí ìgbéraga wọ̀ wá lẹ́wù, ṣe la máa fìwà jọ òun, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ pé èèyàn lè “bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, kó sì ṣubú sínú ìdájọ́ tí a ṣe fún Èṣù.” (1 Tím. 3:6, 7) Kò sẹ́ni tíyẹn ò lè ṣẹlẹ̀ sí, ì bá jẹ́ pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tàbí ọjọ́ pẹ́ tá a ti wà nínú ètò. Ẹni tó bá ń gbéra ga máa ń jọ ara ẹ̀ lójú, tara ẹ̀ nìkan ló sì máa ń rò. Tara wa nìkan ni Sátánì máa ń fẹ́ ká máa rò dípò ká máa ro ti Jèhófà, pàápàá tá a bá bára wa nínú ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ẹnì kan ti fẹ̀sùn èké kàn ẹ́ rí tàbí wọ́n ti hùwà àìdáa sí ẹ lọ́nà kan rí? Sátánì máa fẹ́ kó o bínú sí Jèhófà tàbí kó o bínú sáwọn ará. Sátánì máa fẹ́ kó o ronú pé ohun kan ṣoṣo tó lè yanjú ọ̀rọ̀ náà ni pé kó o ṣe ohun tó o rò pé ó dáa lójú ara ẹ dípò kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jèhófà tó wà nínú Bíbélì.—Oníw. 7:16, 20. w21.06 15 ¶4-5
Thursday, April 20
“Kí gbogbo ẹ̀yin èèyàn ilẹ̀ náà pẹ̀lú jẹ́ onígboyà, kí ẹ sì ṣiṣẹ́” ni Jèhófà wí. “Torí mo wà pẹ̀lú yín,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.—Hág. 2:4.
Jèhófà gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún wòlíì Hágáì. Ó ṣeé ṣe kí Hágáì wà lára àwọn Júù tó pa dà sí Jerúsálẹ́mù láti Bábílónì lọ́dún 537 Ṣ.S.K. Àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n débẹ̀, wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀. (Ẹ́sírà 3:8, 10) Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n rẹ̀wẹ̀sì, tí wọ́n sì dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró torí pé àwọn èèyàn ń ta kò wọ́n. (Ẹ́sírà 4:4; Hág. 1:1, 2) Torí náà lọ́dún 520 Ṣ.S.K., Jèhófà rán Hágáì sí wọn kó lè fún wọn níṣìírí láti parí iṣẹ́ náà. (Ẹ́sírà 6:14, 15) Jèhófà rán Hágáì sáwọn èèyàn rẹ̀ kí wọ́n lè túbọ̀ nígbàgbọ́. Ó dájú pé gbólóhùn náà “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun” máa fún àwọn èèyàn náà lókun. Jèhófà ní ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì alágbára tí wọ́n jẹ́ ọmọ ogun, torí náà kò sídìí fáwọn Júù láti bẹ̀rù. Tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ lé e, wọ́n á ṣàṣeyọrí. w21.09 15 ¶4-5
Friday, April 21
Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.—Jòh. 13:35.
Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbádùn ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan kárí ayé. A yàtọ̀ sáwọn ẹlẹ́sìn tó kù torí pé ìdílé kan tó wà níṣọ̀kan ni wá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti àṣà wa yàtọ̀ síra. Ìfẹ́ tòótọ́ tó wà láàárín wa yìí máa ń hàn láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè wa. Èyí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn rẹ̀. (Jòh. 13:34) Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá pé ká ‘ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara wa.’ (1 Pét. 4:8) Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn ni pé ká máa dárí ji ara wa, ká sì máa fara dà á táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó sí wa. Ọ̀nà míì tá à ń gbà fìfẹ́ hàn ni pé a máa ń ṣoore fún gbogbo àwọn ará ìjọ, a sì máa ń ṣaájò wọn, kódà a máa ń finúure hàn sáwọn tó ṣẹ̀ wá. (Kól. 3:12-14) Irú ìfẹ́ tó lágbára yìí ni ohun àkọ́kọ́ tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. w21.10 22 ¶13-14
Saturday, April 22
Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ máa ń bá a wí dáadáa.—Òwe 13:24.
Tí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, ṣé ìyẹn lè jẹ́ kó ronú pìwà dà? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ló sọ pé ó dáa báwọn alàgbà ṣe yọ àwọn lẹ́gbẹ́. Ìdí ni pé ohun tí wọ́n ṣe yẹn ló pe orí àwọn wálé, tó mú káwọn ronú pìwà dà, káwọn sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (Héb. 12:5, 6) Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí. Olùṣọ́ àgùntàn kan kíyè sí pé ọ̀kan lára àwọn àgùntàn òun ń ṣàìsàn, ó mọ̀ pé ó yẹ kóun ya àgùntàn yẹn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó kù títí tára ẹ̀ fi máa yá. Àmọ́, àwọn àgùntàn máa ń fẹ́ wà pa pọ̀, torí náà, wọ́n lè máa ké tí wọ́n bá yà wọ́n sọ́tọ̀. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ìkà ni olùṣọ́ àgùntàn náà torí pé ó yà á sọ́tọ̀? Rárá o. Ó mọ̀ pé tóun bá jẹ́ kí àgùntàn tó ń ṣàìsàn yẹn wà láàárín àwọn tó kù, àìsàn yẹn máa ràn wọ́n. Torí náà, bó ṣe ya àgùntàn yẹn sọ́tọ̀ dáàbò bo àwọn tó kù. w21.10 10 ¶9-10
Sunday, April 23
Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ rere yín, kí wọ́n sì fògo fún Baba yín tó wà ní ọ̀run.—Mát. 5:16.
Àǹfààní ńlá la ní láti wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn. A fẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn dara pọ̀ mọ́ wa láti máa jọ́sìn Jèhófà. Torí náà, ó yẹ ká ṣọ́ra ká má bàa ṣe ohunkóhun tó máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà tàbí táá mú káwọn èèyàn máa fojú burúkú wo àwa èèyàn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa hùwà lọ́nà tó máa bọlá fún Jèhófà, táá sì mú kó wu àwọn èèyàn láti wá sìn ín. Nígbà míì, àwọn kan lè máa rí sí wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ṣenúnibíni sí wa torí pé à ń ṣègbọràn sí Baba wa ọ̀run. Tí ẹ̀rù bá ń bà wá láti sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn míì ńkọ́? Ó dájú pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ máa ràn wá lọ́wọ́. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n má ṣàníyàn nípa bí wọ́n ṣe máa sọ̀rọ̀ àti ohun tí wọ́n máa sọ. Kí nìdí? Jésù fi kún un pé: “A máa fún yín ní ohun tí ẹ máa sọ ní wákàtí yẹn; torí kì í kàn ṣe ẹ̀yin lẹ̀ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ̀mí Baba yín ló ń gbẹnu yín sọ̀rọ̀.”—Mát. 10:19, 20. w21.09 24 ¶17-18
Monday, April 24
Màá sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni ibi ààbò mi àti odi ààbò mi.”—Sm. 91:2.
Mósè náà lo àfiwé kan tó jọ ọ́ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ibi ààbò. (Sm. 90:1, àlàyé ìsàlẹ̀) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí àkókò ikú Mósè ti sún mọ́lé, ó lo àfiwé míì tó ń fini lọ́kàn balẹ̀. Ó ní: “Ọlọ́run jẹ́ ibi ààbò láti ìgbà àtijọ́, ọwọ́ ayérayé rẹ̀ wà lábẹ́ rẹ.” (Diu. 33:27) Kí ni gbólóhùn náà “ọwọ́ ayérayé rẹ̀ wà lábẹ́ rẹ” jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà? Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dáàbò bò wá, ọkàn wa máa balẹ̀. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ìrẹ̀wẹ̀sì lè mú wa débi tá ò fi ní lókun mọ́. Nírú àwọn àsìkò bẹ́ẹ̀, kí ni Jèhófà máa ń ṣe fún wa? (Sm. 136:23) Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́, ó máa rọra fi apá rẹ̀ gbé wa dìde, kò sì ní jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì mọ́. (Sm. 28:9; 94:18) Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn máa ń jẹ́ ká rántí pé ọ̀nà méjì ló ń gbà ràn wá lọ́wọ́. Àkọ́kọ́, ibi yòówù ká máa gbé, a mọ̀ pé Jèhófà á máa dáàbò bò wá. Ìkejì, Bàbá wa ọ̀run ń fìfẹ́ bójú tó wa. w21.11 6 ¶15-16
Tuesday, April 25
Oríṣiríṣi àdánwò [ti] kó ìdààmú bá yín.—1 Pét. 1:6.
Jésù mọ̀ pé wọ́n máa rẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun jẹ, ìyẹn sì máa dán ìgbàgbọ́ wọn wò. Torí náà, Jésù sọ àpèjúwe kan nínú ìwé Lúùkù tó máa jẹ́ kí wọ́n lè fara dà á. Jésù sọ ìtàn nípa opó kan tó ń lọ sọ́dọ̀ adájọ́ kan tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, kò sì fi adájọ́ náà lọ́rùn sílẹ̀. Ó dá a lójú pé lọ́jọ́ kan, adájọ́ náà máa dá ẹjọ́ òun bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí? Jèhófà kì í ṣe aláìṣòdodo. Jésù sọ pé: “Ṣé kò wá dájú pé Ọlọ́run máa mú kí a dájọ́ bó ṣe tọ́ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń ké pè é tọ̀sántòru?” (Lúùkù 18:1-8) Jésù wá fi kún un pé: “Tí Ọmọ èèyàn bá dé, ṣé ó máa bá ìgbàgbọ́ yìí ní ayé lóòótọ́?” Tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ, àmọ́ tá a ṣe sùúrù tá a sì fara dà á, ìyẹn máa fi hàn pé a nígbàgbọ́ tó lágbára bíi ti opó yẹn. Tá a bá nírú ìgbàgbọ́ tó lágbára bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa jà fún wa láìpẹ́. Bákan náà, ó yẹ ká gbà pé kò sí nǹkan tí àdúrà ò lè ṣe. w21.11 23 ¶12; 24 ¶14
Wednesday, April 26
Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Tó bá ń kíyè sára, tó sì ń pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ.—Sm. 119:9.
Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ṣé ó máa ń ṣe yín nígbà míì bíi pé àwọn ìlànà Jèhófà ti le jù? Ohun tí Sátánì fẹ́ kẹ́ ẹ máa rò gan-an nìyẹn. Ó fẹ́ kẹ́ ẹ máa ronú ṣáá nípa ohun táwọn tó wà lójú ọ̀nà tó fẹ̀ ń ṣe tó sì dà bíi pé wọ́n ń gbádùn ara wọn. Ó fẹ́ kẹ́ ẹ máa ronú pé ẹ ò gbádùn ara yín bí àwọn ọmọ iléèwé yín tàbí àwọn tẹ́ ẹ̀ ń rí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó tún fẹ́ kẹ́ ẹ gbà pé àwọn ìlànà Jèhófà ò jẹ́ kẹ́ ẹ gbádùn ara yín dọ́ba. Àmọ́ ẹ rántí pé Sátánì ò fẹ́ káwọn tó ń rìn lójú ọ̀nà ẹ̀ mọ ibi tí ọ̀nà náà máa já sí. (Mát. 7:13, 14) Àmọ́ ní ti Jèhófà, ó jẹ́ ká mọ̀ pé a máa láyọ̀ tá a bá dúró sójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Sm. 37:29; Àìsá. 35:5, 6; 65:21-23. w21.12 23 ¶6-7
Thursday, April 27
Dárí ji arákùnrin rẹ látọkàn wá.—Mát. 18:35.
A mọ̀ pé ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá, àmọ́ kì í rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ìgbà kan wà tó ṣe àpọ́sítélì Pétérù náà bẹ́ẹ̀. (Mát. 18:21, 22) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló lè ràn wá lọ́wọ́? Àkọ́kọ́, máa ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń dárí ji ìwọ náà. (Mát. 18:32, 33) A ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń dárí jì, síbẹ̀ ó ń dárí jì wá fàlàlà. (Sm. 103:8-10) Lọ́nà kan náà, “àwa náà gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́” àwọn ará wa. Torí náà, ìdáríjì kì í ṣọ̀rọ̀ bóyá ó wù wá tàbí kò wù wá, ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe ni. A gbọ́dọ̀ dárí ji àwọn ará wa tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá. (1 Jòh. 4:11) Ìkejì, ronú lórí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tó o bá dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn ẹni náà máa balẹ̀, ìjọ á wà níṣọ̀kan, wàá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ọkàn tìẹ náà á sì fúyẹ́. (2 Kọ́r. 2:7; Kól. 3:14) Paríparí ẹ̀, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa dárí jini. Má ṣe jẹ́ kí Èṣù da àárín ìwọ àti àwọn ará rú. (Éfé. 4:26, 27) Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé, tá ò bá fẹ́ kó sọ́wọ́ Sátánì, àfi kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́. w21.06 22 ¶11; 23 ¶14
Friday, April 28
Ìwọ lo máa di ọba Ísírẹ́lì. —1 Sám. 23:17.
Ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí Dáfídì máa sá fún ẹ̀mí ẹ̀. Kí lohun náà? Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọba Ísírẹ́lì ló ń wọ́nà àtigbẹ̀mí ẹ̀. Níbi tí Dáfídì ti ń sá lọ, ebi ń pa á, ó wá fẹsẹ̀ kan yà nílùú Nóbù, ó sì ní kí wọ́n fún òun ní búrẹ́dì márùn-ún péré. (1 Sám. 21:1, 3) Nígbà tó sì yá, òun àtàwọn èèyàn ẹ̀ fara pa mọ́ sínú ihò kan. (1 Sám. 22:1) Kí ló fà á tí Ọba Sọ́ọ̀lù fi ń lé Dáfídì kiri, tó sì ń wọ́nà àtigbẹ̀mí ẹ̀? Inú ń bí Sọ́ọ̀lù burúkú burúkú sí Dáfídì, ó sì ń jowú ẹ̀ torí pé àwọn èèyàn gba ti Dáfídì gan-an, wọ́n sì ń yìn ín torí pé ó jẹ́ akin lójú ogun. Yàtọ̀ síyẹn, Sọ́ọ̀lù mọ̀ pé bí òun ṣe sàìgbọràn sí Jèhófà ti jẹ́ kó kọ òun lọ́ba. Ó sì ti yan Dáfídì láti di ọba dípò òun. (1 Sám. 23:16, 17) Torí pé Sọ́ọ̀lù ni ọba Ísírẹ́lì àti pé òun ló ṣì ń darí àwọn ọmọ ogun, àwọn èèyàn ń tì í lẹ́yìn gan-an. Torí náà, Dáfídì ní láti sá fún ẹ̀mí ẹ̀. Ṣé Sọ́ọ̀lù ronú pé òun lè ṣe é kí Dáfídì má di ọba bí Ọlọ́run ṣe sọ? (Àìsá. 55:11) Bíbélì ò sọ, àmọ́ ohun kan dá wa lójú. Ṣe ló dà bí ẹni pé Sọ́ọ̀lù ń bá Ọlọ́run jà, ó sì yẹ kó mọ̀ pé kò sẹ́ni tó máa bá Ọlọ́run jà tó lè borí! w22.01 2 ¶1-2
Saturday, April 29
Nikodémù . . . wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní òru.—Jòh. 3:1, 2.
Jésù ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Gbogbo àyè tó bá ṣí sílẹ̀ ni Jésù fi ń kọ́ àwọn èèyàn, ìyẹn sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. (Lúùkù 19:47, 48) Kí ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀? Àánú tí Jésù ní sí wọn ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ìgbà míì wà tí Jésù kọ́ àwọn èèyàn débi pé òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ “ò ráyè jẹun pàápàá.” (Máàkù 3:20) Nígbà tí ọkùnrin kan wá sọ́dọ̀ Jésù lálẹ́ kó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀, Jésù rí i pé òun kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ lásìkò yẹn. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó kọ́kọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ò di ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Àmọ́ gbogbo àwọn tó tẹ́tí sí i ni Jésù jẹ́rìí fún kúnnákúnná. Lónìí, gbogbo èèyàn ló yẹ káwa náà wàásù fún. (Ìṣe 10:42) Kíyẹn lè ṣeé ṣe, ó yẹ ká ṣe àwọn àyípadà kan lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Dípò ká ní àkókò kan pàtó tó rọ̀ wá lọ́rùn tá a fi ń wàásù fáwọn èèyàn, ṣe ló yẹ ká yí àkókò tá a fi ń wàásù pa dà ká lè túbọ̀ ráwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí wa. w22.01 17 ¶13-14
Sunday, April 30
Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ.—Oníw. 8:9.
Lóde òní ó máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti fọkàn tán àwọn aláṣẹ. Wọ́n ti rí i pé àwọn adájọ́ àtàwọn olóṣèlú máa ń ṣojúure sáwọn olówó àtàwọn èèyàn pàtàkì láwùjọ, wọ́n sì máa ń fi ẹ̀tọ́ àwọn tálákà dù wọ́n. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn olórí ẹ̀sìn kan máa ń hùwà burúkú, ìyẹn ni ò jẹ́ káwọn èèyàn kan fọkàn tán Ọlọ́run mọ́. Torí náà, tẹ́nì kan bá gbà pé ká kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kì í rọrùn fún wa láti ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè fọkàn tán Jèhófà àtàwọn tó ń ṣàbójútó nínú ètò rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe àwọn táà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan ló yẹ kó mọ bá a ṣe lè fọkàn tán Jèhófà àti ètò rẹ̀. Àwa tá a ti ń sin Jèhófà bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún náà yẹ kó fọkàn tán Jèhófà pé kò sígbà tí kì í ṣe nǹkan lọ́nà tó tọ́. Àmọ́ nígbà míì, àwọn nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ tó máa ń dán ìgbàgbọ́ wa wò bóyá a fọkàn tán Jèhófà. w22.02 2 ¶1-2