May
Monday, May 1
Ẹ fara balẹ̀ ronú nípa ẹni tó fara dà á.—Héb. 12:3.
Ká lè túbọ̀ mọ Jésù dáadáa, Jèhófà ṣètò pé kí Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wà nínú Bíbélì. Ìtàn ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ló wà nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere náà. Àwọn ìwé náà jẹ́ ká mọ ohun tí Jésù sọ, ohun tó ṣe àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Àwọn Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin máa ń jẹ́ ká lè “fara balẹ̀ ronú” nípa àpẹẹrẹ Jésù. Torí náà, a lè rí ipasẹ̀ Jésù tó yẹ ká máa tọ̀ nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere náà. Láìsí àní-àní, tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé náà, àá túbọ̀ mọ Jésù dáadáa, ìyẹn á sì mú ká máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. Tá a bá fẹ́ túbọ̀ jàǹfààní látinú àwọn Ìwé Ìhìn Rere, a gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ dáadáa, ká sì ronú jinlẹ̀ lé e lórí, kì í ṣe ká kàn kà á nìkan. (Fi wé Jóṣúà 1:8, àlàyé ìsàlẹ̀.) Kó o lè jàǹfààní ní kíkún, ó ṣe pàtàkì pé kó o fojú inú wò ó bíi pé o wà níbẹ̀, pé ò ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, o sì ń gbọ́ bí nǹkan ṣe ń lọ. Ó tún ṣe pàtàkì kó o ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. w21.04 4-5 ¶11-13
Tuesday, May 2
Àwa ń wàásù Kristi tí wọ́n kàn mọ́gi, lójú àwọn Júù, ó jẹ́ ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀.—1 Kọ́r. 1:23.
Ọ̀pọ̀ ọdún kí Jésù tó wá sáyé ni Jèhófà ti sọ nínú Ìwé Mímọ́ pé wọ́n máa da Mèsáyà fún ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà. (Sek. 11:12, 13) Ìwé Mímọ́ tún sọ pé ẹni tó sún mọ́ Jésù bí iṣan ọrùn ló máa dalẹ̀ rẹ̀. (Sm. 41:9) Kódà, wòlíì Sekaráyà sọ pé: “Kọ lu olùṣọ́ àgùntàn, kí agbo sì tú ká.” (Sek. 13:7) Dípò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí á fi mú káwọn tó lọ́kàn tó dáa kọsẹ̀, ṣe ló mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára nígbà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ sí Jésù lára. Ṣé irú ìṣòro yìí wà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Lóde òní, àwọn ará kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ti fi òtítọ́ sílẹ̀, wọ́n di apẹ̀yìndà, wọ́n sì ń wá bí wọ́n á ṣe mú káwọn míì fi òtítọ́ sílẹ̀. Wọ́n ti sọ ohun tí ò dáa nípa wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tẹlifíṣọ̀n, rédíò àtàwọn ìwé ìròyìn, kódà wọ́n ń pa ògidì irọ́ mọ́ wa. Àmọ́ àwọn tó lọ́kàn tó dáa ò jẹ́ kíyẹn ṣì wọ́n lọ́nà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀.—Mát. 24:24; 2 Pét. 2:18-22. w21.05 11 ¶12; 12-13 ¶18-19
Wednesday, May 3
Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ àárọ̀ tó ń mọ́lẹ̀ sí i títí di ọ̀sán gangan.—Òwe 4:18.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó ní ìmọ̀ tó péye. (Kól. 1:9, 10) Díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà máa ń jẹ́ ká lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́, èyí sì gba pé ká ní sùúrù títí dìgbà tí ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa túbọ̀ yé wa dáadáa. Tí àwọn tó ń ṣe àbójútó nínú ètò Ọlọ́run bá rí i pé ó yẹ ká ṣàtúnṣe ẹ̀kọ́ òtítọ́ kan, wọ́n tètè máa ń ṣe irú àtúnṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó máa ń mú kí ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe àwọn àyípadà kan ni pé wọ́n fẹ́ tẹ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn lọ́rùn tàbí nítorí pé wọ́n fẹ́ ṣe bí ayé ṣe fẹ́. Àmọ́ ní ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a máa ń ṣe àyípadà nítorí ká lè sún mọ́ Ọlọ́run àti pé a fẹ́ máa tẹ̀ lé ọ̀nà tí Jésù ní ká máa gbà jọ́sìn. (Jém. 4:4) Kì í ṣe ohun táráyé ń gbé lárugẹ tàbí ohun táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ló ń mú ká ṣe àyípadà tá à ń ṣe, àmọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a túbọ̀ lóye ló mú ká ṣe àwọn àyípadà yẹn. Ẹ ò rí i pé a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ gan-an!—1 Tẹs. 2:3, 4. w21.10 22 ¶12
Thursday, May 4
Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.—1 Pét. 5:7.
Kí lo lè ṣe tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò rẹ́ni fojú jọ? Máa ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Sm. 55:22) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò rẹ́ni fojú jọ. Tún máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó ronú pé àwọn ò rẹ́ni fojú jọ. (1 Pét. 5:9, 10) Arákùnrin Hiroshi, tó jẹ́ pé òun nìkan ni Ẹlẹ́rìí nínú ìdílé ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Báwọn ará ṣe ń fara dà á tí wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ń fún àwa tá ò ní ẹbí nínú òtítọ́ níṣìírí.” Bákan náà, máa ṣe ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Èyí gba pé kó o máa sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún un. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí àwọn apá táá jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ. Àwọn Kristẹni kan máa ń há àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tuni nínú sórí, bíi Sáàmù 27:10 àti Àìsáyà 41:10. Ohun táwọn míì máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń tẹ́tí sí Bíbélì àtàwọn àpilẹ̀kọ tá a kà sórí ẹ̀rọ tí wọ́n bá ń múra ìpàdé sílẹ̀, ìyẹn kì í jẹ́ kí wọ́n ronú pé àwọn dá wà. w21.06 9-10 ¶5-8
Friday, May 5
O ò ní bẹ̀rù àjálù òjijì.—Òwe 3:25.
Ṣé o ní ẹ̀dùn ọkàn torí èèyàn ẹ kan tó kú? O lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára nínú ìrètí àjíǹde tó o bá ń kà nípa àwọn tá a jí dìde nínú Bíbélì. Àbí kẹ̀, ṣé ẹnì kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ nínú ìdílé ẹ ló ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣèwádìí kó lè dá ẹ lójú pé ọ̀nà tó dáa jù ni Jèhófà máa ń gbà bá wa wí. Ìṣòro yòówù kó o máa kojú, jẹ́ kó mú kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára. Sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún Jèhófà, má ya ara ẹ sọ́tọ̀, ṣe ni kó o túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará. (Òwe 18:1) Tó o bá ń rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ, tíyẹn sì ń jẹ́ kó o máa sunkún, máa ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o fara dà á. (Sm. 126:5, 6) Máa lọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí déédéé, kó o sì máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Yàtọ̀ síyẹn, máa ronú nípa àwọn ohun rere tí Jèhófà máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú. Bó o sì ṣe ń rí bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́, ṣe ni ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ máa lágbára. w21.11 23 ¶11; 24 ¶17
Saturday, May 6
Bákan náà, kò wu Baba mi tó wà ní ọ̀run pé kí ọ̀kan péré nínú àwọn ẹni kékeré yìí ṣègbé.—Mát. 18:14.
Ọ̀nà wo làwa ọmọlẹ́yìn Jésù gbà dà bí àwọn “ẹni kékeré”? Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná. Àwọn wo làwọn èèyàn máa ń kà sí pàtàkì nínú ayé? Àwọn tó lówó, àwọn tó gbajúmọ̀ àtàwọn tó lẹ́nu láwùjọ. Àmọ́, àwa ọmọlẹ́yìn Jésù ò rí bẹ́ẹ̀. Torí náà, àwọn èèyàn máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú wa, wọ́n sì kà wá sí “ẹni kékeré.” (1 Kọ́r. 1:26-29) Síbẹ̀, kì í ṣe ojú tí Jèhófà fi ń wò wá nìyẹn. Kí ló mú kí Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn “ẹni kékeré yìí”? Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bi í pé: “Ní tòótọ́, ta ló tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run?” (Mát. 18:1) Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn Júù gbà pé ó ṣe pàtàkì káwọn wà nípò ọlá, káwọn sì lẹ́nu láwùjọ. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Ohun tó ṣe pàtàkì jù láyé àwọn èèyàn ni bí wọ́n á ṣe gbayì, tí wọ́n á gbajúmọ̀, tí wọ́n á sì lókìkí.” Jésù mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló máa ń bá ara wọn díje, ó sì mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn ọmọlẹ́yìn òun sapá kí wọ́n lè fa ẹ̀mí burúkú yìí tu lọ́kàn wọn. w21.06 20 ¶2; 21 ¶6, 8; 22 ¶9
Sunday, May 7
Òróró àti tùràrí máa ń mú ọkàn yọ̀; bẹ́ẹ̀ ni adùn ọ̀rẹ́ máa ń wá látinú ìmọ̀ràn àtọkànwá.—Òwe 27:9.
Alàgbà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àpẹẹrẹ tó dáa ló sì fi lélẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó rí i pé ó yẹ kóun gba àwọn ará ní Tẹsalóníkà nímọ̀ràn, ó ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ nínú lẹ́tà tó kọ sí wọn, ó kọ́kọ́ gbóríyìn fún wọn nítorí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ìsapá wọn àti ìfaradà wọn. Pọ́ọ̀lù tún ronú nípa ohun tí wọ́n ń dojú kọ àti bí wọ́n ṣe ń fara da inúnibíni. (1 Tẹs. 1:3; 2 Tẹs. 1:4) Kódà, ó sọ fáwọn ará yẹn pé àpẹẹrẹ tó dáa ni wọ́n jẹ́ fáwọn Kristẹni míì. (1 Tẹs. 1:8, 9) Ẹ wo bí inú wọn ṣe máa dùn tó bí wọ́n ṣe ń ka lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù fi gbóríyìn fún wọn! Kò sí àní-àní pé Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn ará yẹn gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi lè gbà wọ́n nímọ̀ràn tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú lẹ́tà méjèèjì tó kọ sí wọn.—1 Tẹs. 4:1, 3-5, 11; 2 Tẹs. 3:11, 12. w22.02 15 ¶6
Monday, May 8
Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́.—Ìfi. 21:4.
Sátánì máa ń mú kí àwọn ẹlẹ́sìn èké kọ́ni pé ìkà ni Ọlọ́run àti pé òun ló ń fa ìyà tó ń jẹ aráyé. Táwọn ọmọdé bá kú, àwọn kan máa ń sọ pé Ọlọ́run ló mú wọn lọ torí pé ó nílò àwọn áńgẹ́lì míì lọ́run. Ẹ ò rí i pé irọ́ burúkú nìyẹn! Àwa mọ ohun tó jẹ́ òótọ́. A kì í dá Ọlọ́run lẹ́bi tá a bá ń ṣàìsàn tàbí téèyàn wa kan bá kú. Dípò ìyẹn, a nígbàgbọ́ pé láìpẹ́, Jèhófà máa mú àìsàn kúrò, á sì jí àwọn òkú dìde. Torí náà, a máa ń fayọ̀ sọ fún gbogbo èèyàn pé Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà. Ìyẹn sì ń jẹ́ kí Jèhófà fún ẹni tó ń pẹ̀gàn rẹ̀ lésì. (Òwe 27:11) Ọlọ́run aláàánú ni Jèhófà. Ó máa ń dùn ún tó bá rí i pé à ń jìyà bóyá torí inúnibíni, àìsàn tàbí àìpé wa. (Sm. 22:23, 24) Jèhófà mọ̀ ọ́n lára tá a bá ń jìyà, ó wù ú láti fòpin sí i, á sì fòpin sí i.—Fi wé Ẹ́kísódù 3:7, 8; Àìsáyà 63:9. w21.07 9-10 ¶9-10
Tuesday, May 9
O . . . fi ògo àti ọlá ńlá dé e ládé.—Sm. 8:5.
Àǹfààní tó ga jù lọ táwọn onígbọràn máa gbádùn láìpẹ́ ni pé wọ́n á nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n á sì máa jọ́sìn ẹ̀ títí láé. Gbogbo àjálù tó ti wáyé látìgbà tí Ádámù àti Éfà ti fi ìdílé Jèhófà sílẹ̀ ni Jésù máa ṣàtúnṣe sí. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ni Jèhófà máa jí dìde, á fún wọn ní ìlera pípé, á sì fún wọn láǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú ayé tó ti di Párádísè. (Lúùkù 23:42, 43) Bí àwọn tó wà nínú ìdílé Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ṣe túbọ̀ ń di pípé, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn máa ní “ògo àti ọlá ńlá” tí Dáfídì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Tó o bá wà lára “ogunlọ́gọ̀ èèyàn,” ìrètí àgbàyanu lo ní. (Ìfi. 7:9) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì fẹ́ kó o wà nínú ìdílé òun títí láé. Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti múnú ẹ̀ dùn. Jẹ́ kí àwọn ìlérí Jèhófà máa wà lọ́kàn ẹ lójoojúmọ́. Lákòótán, mọyì àǹfààní tó o ní pé o wà lára àwọn tó ń jọ́sìn Baba wa ọ̀run kó o sì jẹ́ kí inú ẹ máa dùn pé wàá láǹfààní láti máa sìn ín títí láé àti láéláé! w21.08 7 ¶18-19
Wednesday, May 10
A máa kórè rẹ̀ tí a ò bá jẹ́ kó rẹ̀ wá.—Gál. 6:9.
Ọ̀pọ̀ ọdún ni wòlíì Jeremáyà fi wàásù fáwọn èèyàn tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì tún ń ta kò ó. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá a nítorí “èébú àti yẹ̀yẹ́” látọ̀dọ̀ àwọn alátakò rẹ̀, ó sì rò pé òun ò ní lè ṣiṣẹ́ ìwàásù mọ́. (Jer. 20:8, 9) Àmọ́, Jeremáyà ò jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì mú òun! Kí ló jẹ́ kó borí èrò tí ò dáa tó ní, tó sì ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀? Ohun pàtàkì méjì ló ràn án lọ́wọ́. Àkọ́kọ́, iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán Jeremáyà sí àwọn èèyàn jẹ́ kí wọ́n ní “ìrètí” pé “ọjọ́ ọ̀la” máa dáa. (Jer. 29:11) Ìkejì, Jèhófà ti yan Jeremáyà láti máa sọ̀rọ̀ nípa orúkọ òun. (Jer. 15:16) Àwa náà ń wàásù fáwọn èèyàn pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, a sì tún jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó ń wàásù orúkọ rẹ̀. Tá a bá gbájú mọ́ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì yìí, àá máa láyọ̀ bóyá àwọn èèyàn gbọ́ wa tàbí wọn ò gbọ́. Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì mú yín tẹ́ ẹ bá rí i pé àwọn tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò tètè tẹ̀ síwájú. Iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn gba sùúrù.—Jém. 5:7, 8. w21.10 27 ¶12-13
Thursday, May 11
Ẹ jẹ́ kí àwa náà ju gbogbo ẹrù tó wúwo nù àti ẹ̀ṣẹ̀ tó máa ń wé mọ́ wa tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn.—Héb. 12:1.
Láìka bó ti pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà bọ̀, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ máa lágbára. Kí nìdí? Ìdí ni pé tá ò bá ṣọ́ra, ìgbàgbọ́ wa lè bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn. Ẹ rántí pé ohun tó ń jẹ́ kéèyàn nígbàgbọ́ ni ẹ̀rí tó dájú nípa àwọn ohun gidi tí a kò rí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, téèyàn ò bá rí nǹkan, èèyàn lè tètè gbàgbé rẹ̀. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé àìnígbàgbọ́ jẹ́ “ẹ̀ṣẹ̀ tó máa ń wé mọ́ wa tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn.” Kí wá la lè ṣe tí ìgbàgbọ́ wa ò fi ní jó rẹ̀yìn? (2 Tẹs. 1:3) Lákọ̀ọ́kọ́, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kó o sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìgbàgbọ́ jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí. (Gál. 5:22, 23) Ẹ̀mí mímọ́ nìkan ló lè mú ká nígbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá, òun náà sì ni ò ní jẹ́ kígbàgbọ́ wa jó rẹ̀yìn. Tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó dájú pé ó máa fún wa. (Lúùkù 11:13) Kódà, a lè sọ fún un nínú àdúrà wa pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.” (Lúùkù 17:5) Bákan náà, máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé.—Sm. 1:2, 3. w21.08 18-19 ¶16-18
Friday, May 12
Ewú orí jẹ́ adé ẹwà.—Òwe 16:31.
Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn àgbàlagbà lè ṣe nínú ètò Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè ṣe tó bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ ìrírí tí wọ́n ti ní ò ṣeé fowó rà. Torí náà, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà lè lo àwọn àgbàlagbà láti ṣe nínú ìjọ. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà títí wọ́n fi dàgbà ló wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan bí ẹni ọgọ́rin (80) ọdún ni Mósè nígbà tí Jèhófà yàn án láti jẹ́ wòlíì àti aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáníẹ́lì ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún (90) ọdún, síbẹ̀ Jèhófà ṣì ń lò ó gẹ́gẹ́ bíi wòlíì. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí àpọ́sítélì Jòhánù ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún (90) ọdún nígbà tí Jèhófà mí sí i láti kọ ìwé Ìfihàn. Bíbélì ò sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa Síméónì bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pè é ní “olódodo àti ẹni tó ní ìfọkànsìn.” Àmọ́ Jèhófà kíyè sí ọkùnrin olóòótọ́ yìí, ó sì fún un láǹfààní láti rí Jésù nígbà tó wà ní kékeré, kó sì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Jésù àti ìyá rẹ̀.—Lúùkù 2:22, 25-35. w21.09 3-4 ¶5-7
Saturday, May 13
Jèhófà, mi ò gbéra ga, . . . bẹ́ẹ̀ ni mi ò máa lé nǹkan ńláńlá.—Sm. 131:1.
Àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má di pé wọ́n ń fi àwọn ọmọ wọn wéra tàbí kí wọ́n ní káwọn ọmọ wọn ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn lè rẹ̀wẹ̀sì. (Éfé. 6:4) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sachiko sọ pé: “Màmá mi fẹ́ kí n máa gba gbogbo máàkì nígbà ìdánwò, ìyẹn ò sì ṣeé ṣe. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá tí mo ti jáde ilé ẹ̀kọ́, ó ṣì máa ń ṣe mí bíi pé inú Jèhófà ò lè dùn sí mi bí mo tiẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀.” Ọba Dáfídì sọ pé òun ò “lé nǹkan ńláńlá” tàbí àwọn nǹkan tó kọjá agbára òun. Torí pé ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ọkàn ẹ̀ balẹ̀, ó sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. (Sm. 131:2) Kí làwọn òbí lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yìí? Àwọn òbí tó nírẹ̀lẹ̀ kì í ṣe kọjá ohun tí wọ́n lè ṣe, wọn kì í sì í retí pé káwọn ọmọ wọn ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ. Táwọn òbí bá mọ ohun tí ọmọ wọn lè ṣe àtohun tí ò lè ṣe, wọ́n á fi í lọ́kàn balẹ̀, wọn ò sì ní máa retí pé kó ṣe ohun tágbára rẹ̀ ò gbé. w21.07 21-22 ¶5-6
Sunday, May 14
Kálukú ló máa ru ẹrù ara rẹ̀.—Gál. 6:5.
Jèhófà ti fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní òmìnira láti yan ohun tá a fẹ́. Ìyẹn fi hàn pé àwa fúnra wa la máa pinnu bóyá a máa sìn ín tàbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí tí ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló tọ́ àwọn ọ̀dọ́ kan dàgbà, síbẹ̀ àwọn ọ̀dọ́ náà pinnu láti sin Jèhófà, wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ sí i. Àwọn ọ̀dọ́ míì sì wà tó jẹ́ pé àwọn òbí wọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wọn. Síbẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ náà fi Jèhófà sílẹ̀ nígbà tí wọ́n dàgbà. Kókó ibẹ̀ ni pé, kálukú ló máa pinnu bóyá òun máa sin Jèhófà. (Jóṣ. 24:15) Torí náà, ẹ̀yin òbí tọ́mọ yín ti fi Jèhófà sílẹ̀, ẹ má ṣe ronú láé pé ẹ̀yin lẹ fa ohun tó ṣẹlẹ̀ náà! Nígbà míì, bàbá kan tàbí ìyá kan lè fi Jèhófà àti ìdílé ẹ̀ sílẹ̀. (Sm. 27:10) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kì í rọrùn fáwọn ọmọ torí pé ojú òbí làwọn ọmọ máa ń wò, àpẹẹrẹ wọn sì ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé. Ẹ̀yin ọ̀dọ́, tó bá jẹ́ pé wọ́n ti yọ ọ̀kan nínú àwọn òbí yín lẹ́gbẹ́, ẹ kú ìfaradà, a mọ̀ pé kò rọrùn fún yín. Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé Jèhófà mọ bọ́rọ̀ náà ṣe dùn yín tó. Ó nífẹ̀ẹ́ yín, ó sì mọrírì bẹ́ ẹ ṣe jẹ́ adúróṣinṣin láìka ohun tó ṣẹlẹ̀ sí. Rántí pé, ìwọ kọ́ lo lẹ̀bi ìpinnu táwọn òbí ẹ ṣe. w21.09 27 ¶5-7
Monday, May 15
Àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí.—Héb. 12:6.
Tí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, ṣe lẹni náà dà bí àgùntàn tó ní àìsàn tó lè ran àwọn àgùntàn tó kù. Ìdí ni pé òun náà ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí. (Jém. 5:14) Bí àwọn àìsàn kan ṣe máa ń ràn, bẹ́ẹ̀ náà ni àìsàn tẹ̀mí ṣe máa ń ràn. Nítorí náà, ó pọn dandan nígbà míì kí wọ́n ya ẹni tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí sọ́tọ̀, kó má bàa kó àìsàn tẹ̀mí náà ran àwọn míì nínú ìjọ. Ìbáwí yẹn fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó wà nínú ìjọ, kò sì fẹ́ kí ohunkóhun ṣẹlẹ̀ sí wọn. Bákan náà, ìbáwí yẹn lè pe orí oníwà àìtọ́ náà wálé, kó sì ronú pìwà dà. Ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà ṣì lè máa wá sípàdé kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lè pa dà lágbára. Ó tún lè gba àwọn ìtẹ̀jáde tó bá fẹ́ kà, kó sì wo ètò JW Broadcasting®. Táwọn alàgbà bá kíyè sí i pé ó ti ń yí pa dà, wọ́n lè máa fún un nímọ̀ràn látìgbàdégbà, kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n sì gbà á pa dà sínú ìjọ. w21.10 10 ¶9, 11
Tuesday, May 16
Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ló máa wọ Ìjọba ọ̀run.—Mát. 7:21.
Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé ọ̀nà táwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ gbà jọ́sìn. Bí àpẹẹrẹ, a ní àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ wa. Ètò tá a ṣe yìí bá ohun táwọn àpọ́sítélì ṣe mu nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. (Fílí. 1:1; Títù 1:5) Bákan náà, à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ táwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ fi lélẹ̀ torí pé à ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó, lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ àti bá a ṣe ń dáàbò bo ìjọ kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà. (Ìṣe 15:28, 29; 1 Kọ́r. 5:11-13; 6:9, 10; Héb. 13:4) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “ìgbàgbọ́ kan” ló wà tí Ọlọ́run fọwọ́ sí. (Éfé. 4:4-6) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a wà lára àwọn èèyàn Jèhófà àti pé a mọ òtítọ́ nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé lọ́jọ́ iwájú! Torí náà, ẹ jẹ́ ká di ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó dá wa lójú mú ṣinṣin. w21.10 22-23 ¶15-17
Wednesday, May 17
Ẹ dúró sáyè yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà lórí yín.—2 Kíró. 20:17.
Ọba Jèhóṣáfátì dojú kọ ìṣòro ńlá kan. Àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an láti Ámónì, Móábù àti agbègbè olókè Séírì wá gbéjà ko Jèhóṣáfátì, ìdílé rẹ̀ àtàwọn èèyàn Júdà. (2 Kíró. 20:1, 2) Kí ni Jèhóṣáfátì wá ṣe? Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa ran òun lọ́wọ́ àti pé ó máa fún òun lókun. Àdúrà ìrẹ̀lẹ̀ tí Jèhóṣáfátì gbà nínú 2 Kíróníkà 20:5-12 fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Bàbá rẹ̀ ọ̀run gan-an. Jèhófà rán ọmọ Léfì kan tó ń jẹ́ Jáhásíẹ́lì láti bá Jèhóṣáfátì sọ̀rọ̀. Ohun tó sọ ló wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní. Jèhóṣáfátì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ó sì ṣe ohun tí Jèhófà sọ. Nígbà tóun àtàwọn èèyàn ẹ̀ jáde lọ kojú àwọn ọ̀tá, kì í ṣe àwọn akínkanjú jagunjagun ló kó síwájú, àmọ́ àwọn akọrin tí kò mú ohun ìjà kankan lọ́wọ́ ló kó síwájú. Jèhófà mú ìlérí tó ṣe fún Jèhóṣáfátì ṣẹ, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn.—2 Kíró. 20:18-23. w21.11 15-16 ¶6-7
Thursday, May 18
Nítorí ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ ni ò jẹ́ ká ṣègbé, nítorí àánú rẹ̀ kò ní dópin láé.—Ìdárò 3:22.
Tá a bá kojú ìṣòro, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ má bàa bà jẹ́. (2 Kọ́r. 4:7-9) Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà á máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa nìṣó, torí onísáàmù fi dá wa lójú pé, “ojú Jèhófà ń ṣọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀, àwọn tó ń dúró de ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.” (Sm. 33:18-22) Kó tó di pé a di ìránṣẹ́ Jèhófà la ti ń gbádùn ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí aráyé. Àmọ́, lẹ́yìn tá a di ìránṣẹ́ rẹ̀, a wá ń gbádùn ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa yìí ló jẹ́ kó fà wá mọ́ra, tó sì ń mú kó máa dáàbò bò wá. Jèhófà á máa wà pẹ̀lú wa nígbà gbogbo, á sì mú àwọn ìlérí tó ṣe fún wa ṣẹ. Ẹ ò rí i pé Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ ọ̀rẹ́ òun títí láé! (Sm. 46:1, 2, 7) Torí náà, ìṣòro yòówù ká máa kojú, Jèhófà á fún wa lókun ká lè jẹ́ olóòótọ́. w21.11 7 ¶17-18
Friday, May 19
Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà.—Kól. 3:13.
Ọ̀pọ̀ lára wa ti rí ẹni tó di ẹnì kejì rẹ̀ sínú fún ọ̀pọ̀ ọdún, irú bí ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, ọmọ ilé ìwé ẹ̀, mọ̀lẹ́bí ẹ̀ àti ará ilé ẹ̀. Ṣé ẹ rántí pé àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù dì í sínú? Nígbà tó yá, ìyẹn mú kí wọ́n hùwà ìkà sí i. (Jẹ́n. 37:2-8, 25-28) Ẹ ò rí i pé ìwà Jósẹ́fù yàtọ̀, kò sì bínú sí wọn! Nígbà tó dé ipò àṣẹ, tó sì yẹ kó gbẹ̀san lára wọn, kò ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fàánú hàn sí wọn, kò sì dì wọ́n sínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Léfítíkù 19:18. (Jẹ́n. 50:19-21) Ohun tá a rí kọ́ lára Jósẹ́fù ni pé tá a bá fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ó yẹ ká máa dárí jini dípò ká di ara wa sínú tàbí ká máa gbẹ̀san. Jésù rọ̀ wá pé ká máa dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá. (Mát. 6:9, 12) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ má ṣe fúnra yín gbẹ̀san, ẹ̀yin olùfẹ́.”—Róòmù 12:19. w21.12 11 ¶13-14
Saturday, May 20
Ó ń fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ní ohun tí ọkàn wọn ń fẹ́; Ó ń gbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́, ó sì ń gbà wọ́n.—Sm. 145:19.
Ní alẹ́ Nísàn 14, 33 S.K., Jésù lọ sínú ọgbà Gẹ́tísémánì. Nígbà tó débẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ fún Jèhófà. (Lúùkù 22:39-44) Àsìkò tí nǹkan nira fún Jésù yẹn ló “rawọ́ ẹ̀bẹ̀ [pẹ̀lú] ẹkún tó rinlẹ̀ àti omijé.” (Héb. 5:7) Kí ni Jésù sọ pé kí Jèhófà ṣe fún òun ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀? Ó gbàdúrà pé kí Jèhófà fún òun lókun kí òun lè ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, kóun sì jẹ́ olóòótọ́ dópin. Jèhófà gbọ́ àdúrà àtọkànwá tí Ọmọ rẹ̀ gbà, ó sì rán áńgẹ́lì kan láti fún un lókun. Jésù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, kí òun sì ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́. Jèhófà fetí sí àdúrà àtọkànwá tí Jésù gbà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tó ṣe pàtàkì jù sí Jésù ni bó ṣe máa jẹ́ olóòótọ́ sí Bàbá rẹ̀ àti bó ṣe máa dá orúkọ Bàbá rẹ̀ láre. Tó bá jẹ́ ohun tó jẹ àwa náà lógún nìyẹn, Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa.—Sm. 145:18. w22.01 18 ¶15-17
Sunday, May 21
Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn . . . , ẹ máa kọ́ wọn.—Mát. 28:19, 20.
Ọ̀pọ̀ èèyàn kórìíra wa torí pé a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, wọ́n retí pé ó yẹ ká máa dìbò. Àmọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere sí wa pé lójú Jèhófà, tá a bá yan èèyàn láti máa ṣàkóso wa, ṣe là ń kọ Jèhófà sílẹ̀. (1 Sám. 8:4-7) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn retí pé ó yẹ ká máa kọ́ ilé ìwé àti ilé ìwòsàn, ká sì máa ṣe àwọn nǹkan míì fún ìdàgbàsókè ìlú. Inú wọn ò dùn torí pé iṣẹ́ ìwàásù la gbájú mọ́ dípò ká wá bá a ṣe máa yanjú ìṣòro ayé yìí. Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀? (Mát. 7:21-23) Ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wa ni bá a ṣe máa ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn nǹkan tó ń lọ lágbo òṣèlú àtàwọn nǹkan míì pín ọkàn wa níyà. A nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ wá lógún. Àmọ́, ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. w21.05 7 ¶19-20
Monday, May 22
Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira.—2 Tím. 3:1.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn aláṣẹ lónìí sọ pé Ọlọ́run làwọn ń sìn, síbẹ̀ wọn ò fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Torí náà bíi ti ìgbà ayé Jésù, àwọn aláṣẹ lónìí ń ta ko Ẹni Àmì Òróró Jèhófà bí wọ́n ṣe ń ṣenúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀. (Ìṣe 4:25-28) Kí ni Jèhófà wá ṣe? Sáàmù 2:10-12 sọ pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ lo ìjìnlẹ̀ òye; ẹ gba ìtọ́sọ́nà, ẹ̀yin onídàájọ́ ayé. Ẹ fi ìbẹ̀rù sin Jèhófà, kí inú yín sì máa dùn nínú ìbẹ̀rù. Ẹ bọlá fún ọmọ náà, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run máa bínú, ẹ sì máa ṣègbé kúrò lójú ọ̀nà, nítorí ìbínú Rẹ̀ tètè máa ń ru. Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó fi Í ṣe ibi ààbò.” Torí pé Jèhófà jẹ́ onínúure, ó fún àwọn alátakò yìí láǹfààní láti yí pa dà, kí wọ́n sì fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ àkókò ti ń lọ. (Àìsá. 61:2) Ó ti wá di kánjúkánjú báyìí fáwọn èèyàn láti mọ òtítọ́ kí wọ́n sì fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. w21.09 15-16 ¶8-9
Tuesday, May 23
Tí a bá ti ní oúnjẹ àti aṣọ, àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ wa lọ́rùn.— 1 Tím. 6:8.
Pọ́ọ̀lù sọ pé ká jẹ́ káwọn nǹkan tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn. (Fílí. 4:12) Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa ni àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà kì í ṣe àwọn nǹkan tara tá a ní. (Háb. 3:17, 18) Àpẹẹrẹ kan lohun tí Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n ti lo ogójì ọdún nínú aginjù. Ó sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o ṣe. . . . Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wà pẹ̀lú rẹ jálẹ̀ ogójì (40) ọdún yìí, o ò sì ṣaláìní ohunkóhun.” (Diu. 2:7) Jálẹ̀ gbogbo ogójì ọdún yẹn, Jèhófà bójú tó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ń fún wọn ní mánà jẹ. Bákan náà, aṣọ wọn ò gbó, ìyẹn àwọn aṣọ tí wọ́n mú kúrò ní Íjíbítì. (Diu. 8:3, 4) Inú Jèhófà máa dùn tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn. Ó fẹ́ ká mọyì àwọn nǹkan tí òun ń ṣe fún wa, ká gbà pé ìbùkún látọ̀dọ̀ òun ni wọ́n jẹ́, ká sì fi hàn pé a moore. w22.01 5 ¶10-11
Wednesday, May 24
Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.—Òwe 3:5.
Ẹ̀yin ọkọ, ọwọ́ yín ló wà láti bójú tó ìdílé yín, torí náà ẹ ṣiṣẹ́ kára láti pèsè ohun tí wọ́n nílò, kẹ́ ẹ sì dáàbò bò wọ́n. Tí ìṣòro bá dé, ẹ lè máa rò ó pé ẹ mọ bẹ́ ẹ ṣe máa dá yanjú ìṣòro náà. Àmọ́ kò yẹ kẹ́ ẹ rò bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kẹ́ ẹ dá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn yín lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ gbàdúrà pẹ̀lú ìyàwó yín látọkàn wá. Ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kẹ́ ẹ máa ṣèwádìí nínú àwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run ṣe, kẹ́ ẹ sì máa fi àwọn ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sílò, ìyẹn máa fi hàn pé ẹ̀ ń wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Àwọn kan lè má fara mọ́ ìpinnu tẹ́ ẹ ṣe torí pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. Wọ́n lè máa sọ fún yín pé ohun tó máa dáàbò bo ìdílé yín jù ni tẹ́ ẹ bá lówó àtàwọn nǹkan ìní tara. Àmọ́, ẹ rántí àpẹẹrẹ Ọba Jèhóṣáfátì. (2 Kíró. 20:1-30) Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, èyí sì hàn nínú gbogbo ohun tó ṣe. Bí Jèhófà ṣe dúró ti Jèhóṣáfátì olóòótọ́, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa dúró ti ẹ̀yin náà.—Sm. 37:28; Héb. 13:5. w21.11 15 ¶6; 16 ¶8
Thursday, May 25
Ọlọ́run . . . kì í ṣe ojúsàájú.—Diu. 32:4.
Torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, ó máa ń wù wá ká ṣe ohun tó tọ́ sáwọn èèyàn. (Jẹ́n. 1:26) Àmọ́ torí pé a jẹ́ aláìpé, a lè ṣi ẹjọ́ dá tá a bá tiẹ̀ rò pé a mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ẹ rántí pé inú Jónà ò dùn nígbà tí Jèhófà fàánú hàn sáwọn ará Nínéfè? (Jónà 3:10–4:1) Àmọ́ kí lohun tí Jèhófà ṣe yìí yọrí sí? Èyí jẹ́ kí àwọn ará ìlú Nínéfè tí iye wọn ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) lọ, tí wọ́n sì ti ronú pìwà dà rí ìgbàlà! Ẹ ò rí i pé nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Jónà ló ṣèdájọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tí kò tọ́, kì í ṣe Jèhófà. Kò pọn dandan kí Jèhófà ṣàlàyé fáwa èèyàn ìdí tó fi ṣe àwọn nǹkan kan. Lóòótọ́, Jèhófà fàyè gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nígbà àtijọ́ láti sọ èrò wọn lórí ohun tó ṣe tàbí ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ṣe. (Jẹ́n. 18:25; Jónà 4:2, 3) Àmọ́ nígbà míì, ó máa ń sọ ìdí tó fi ṣe àwọn nǹkan kan fún wọn. (Jónà 4:10, 11) Síbẹ̀, kò pọn dandan kí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa bóyá a fọwọ́ sóhun tóun fẹ́ ṣe tàbí ohun tóun ti ṣe.—Àìsá. 40:13, 14; 55:9. w22.02 3-4 ¶5-6
Friday, May 26
Kí ẹni tó tóbi jù láàárín yín dà bí ẹni tó kéré jù, kí ẹni tó jẹ́ aṣáájú sì dà bí ẹni tó ń ṣe ìránṣẹ́.—Lúùkù 22:26.
Tá a bá “gbà pé àwọn míì sàn jù” wá lọ, á rọrùn fún wa láti hùwà bí “ẹni tó kéré jù.” (Fílí. 2:3) Tá a bá ń sapá gan-an láti máa hùwà bí ẹni tó kéré jù, a ò ní mú àwọn míì kọsẹ̀. Gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló sàn jù wá lọ lọ́nà kan tàbí òmíì. Ó máa rọrùn fún wa láti gbà bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé ibi tí wọ́n dáa sí là ń wò. Ó ṣe pàtàkì ká fi ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kọ́ríńtì sílò. Ó ní: “Ta ló mú ọ yàtọ̀ sí ẹlòmíràn? Ní tòótọ́, kí lo ní tí kì í ṣe pé o gbà á? Tó bá jẹ́ pé ńṣe lo gbà á lóòótọ́, kí ló dé tí ò ń fọ́nnu bíi pé kì í ṣe pé o gbà á?” (1 Kọ́r. 4:7) Kò yẹ ká máa ṣe ohun táá mú káwọn míì máa pàfiyèsí sí wa ṣáá tàbí táá mú ká máa ronú pé a sàn jù wọ́n lọ. Bí àpẹẹrẹ, tí arákùnrin kan bá mọ bí wọ́n ṣe ń sọ àsọyé tó ń wọni lọ́kàn tàbí tí arábìnrin kan mọ bí wọ́n ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, dípò tí wọ́n á fi jẹ́ káwọn èèyàn máa kan sárá sí wọn, Jèhófà ló yẹ kí wọ́n máa gbé gbogbo ògo náà fún láìjáfara. w21.06 22 ¶9-10
Saturday, May 27
Fún irúgbìn rẹ . . . má sì dẹwọ́.—Oníw. 11:6.
Ó túbọ̀ ń nira gan-an fún ọ̀pọ̀ àwọn ará wa láti bá àwọn èèyàn nílé. Ilé tó ní àwọn ẹ̀ṣọ́ lẹ́nu géètì tàbí àwọn àdúgbò tí wọ́n máa ń ti géètì rẹ̀ pọ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù àwọn akéde kan. Láwọn agbègbè yìí, àwọn ẹ̀ṣọ́ kì í jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé àfi tí onítọ̀hún bá ní àdéhùn pẹ̀lú ẹnì kan tó ń gbé ibẹ̀. Ní ti àwọn akéde míì, wọn kì í sábà bá àwọn èèyàn nílé tàbí kó jẹ́ pé agbègbè táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí ni wọ́n ti ń wàásù. Nígbà míì, àwọn akéde yìí lè rin ìrìn àrìnwọ́dìí láti wá ẹnì kan lọ, síbẹ̀ kí wọ́n má bá a nílé. Ìṣòro yòówù ká máa kojú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ẹ má jẹ́ kó sú wa. Gbìyànjú láti wàásù lákòókò tó yàtọ̀ síra. A máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn bá sọ̀rọ̀ tá a bá lọ lásìkò tá a mọ̀ pé wọ́n máa wà nílé. Ó ṣe tán, ilé làbọ̀ sinmi oko. Ọ̀pọ̀ àwọn ará máa ń lọ sóde ẹ̀rí ní ọ̀sán tàbí lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ torí wọ́n mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa wà nílé lásìkò yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, ara máa ń tu àwọn èèyàn lásìkò yẹn, wọ́n sì máa ń fàyè sílẹ̀ ká lè bá wọn sọ̀rọ̀. w21.05 15 ¶5, 7
Sunday, May 28
Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, torí pé àṣẹ èèyàn ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni.—Máàkù 7:7.
Ṣé irú ìṣòro yìí wà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Inú máa ń bí ọ̀pọ̀ èèyàn tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò bá bá wọn ṣe ayẹyẹ tí kò bá Bíbélì mu bí ọjọ́ ìbí àti Kérésìmesì. Àwọn míì máa ń bínú sí wa torí pé a kì í lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ orílẹ̀-èdè tàbí àwọn àṣà ìsìnkú tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Àwọn tó ń bínú sí wa torí àwọn nǹkan yìí lè ronú pé ọ̀nà tó tọ́ làwọn ń gbà jọ́sìn Ọlọ́run. Àmọ́, kò sí bí wọ́n ṣe lè múnú Ọlọ́run dùn tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ dípò ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni. (Máàkù 7:8, 9) Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀? A gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà. (Sm. 119:97, 113, 163-165) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò ní lọ́wọ́ sí àṣà èyíkéyìí tó kórìíra. Nípa bẹ́ẹ̀, a ò ní nífẹ̀ẹ́ ohunkóhun míì ju Jèhófà lọ. w21.05 6 ¶15-16
Monday, May 29
Máa ronú bó ṣe tọ́ nínú ohun gbogbo, fara da ìnira, ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere.—2 Tím. 4:5.
Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ yìí sílò? A lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, tá à ń gbàdúrà nígbà gbogbo, tá a sì jẹ́ kọ́wọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa. (2 Tím. 4:4) Tí ìgbàgbọ́ wa bá lágbára, a ò ní ṣiyèméjì tá a bá gbọ́ ìròyìn tí ò dáa nípa àwọn ará wa. (Àìsá. 28:16) Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ará wa, a ò ní jẹ́ kí àwọn tó ti fi òtítọ́ sílẹ̀ mú wa kọsẹ̀. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ọ̀pọ̀ ò tẹ́tí sí Jésù, wọn ò sì gbà pé òun ni Mèsáyà. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ tẹ́tí sí i, wọ́n sì dọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Ó kéré tán, ẹnì kan nínú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn dọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ àti “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà.” (Ìṣe 6:7; Mát. 27:57-60; Máàkù 15:43) Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ ni ò jẹ́ kí ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú wọn kọsẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, wọ́n sì dì í mú ṣinṣin. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ; kò sí ohun tó lè mú wọn kọsẹ̀.”—Sm. 119:165. w21.05 13 ¶20-21
Tuesday, May 30
À ń sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.—2 Kọ́r. 12:9.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé kì í ṣe agbára òun lòun fi ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, okun tí Jèhófà fún òun ló mú kó ṣeé ṣe. Jèhófà tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún Pọ́ọ̀lù lágbára láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe inúnibíni sí i, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n, ó sì kojú àwọn ìṣòro míì. Tímótì náà gbára lé Jèhófà kó lè ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú. Àwọn ìgbà kan wà tí Tímótì wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù lẹ́nu ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù tún máa ń rán an lọ sáwọn ìjọ kó lè fún wọn níṣìírí. (1 Kọ́r. 4:17) Tímótì lè máa ronú pé òun ò kúnjú ìwọ̀n, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ torí ẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ṣe gbà á níyànjú pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fojú ọmọdé wò ọ́ rárá.” (1 Tím. 4:12) Kò mọ síbẹ̀ o, lásìkò yẹn, Tímótì náà ní ẹ̀gún kan nínú ara ẹ̀, ìyẹn ‘àìsàn tó ń ṣe é lemọ́lemọ́.’ (1 Tím. 5:23) Àmọ́ ó dá Tímótì lójú pé Jèhófà máa tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún òun lókun kí òun lè máa wàásù nìṣó, kóun sì máa fún àwọn ará níṣìírí.—2 Tím. 1:7. w21.05 21 ¶6-7
Wednesday, May 31
Tọ́jú àwọn àgùntàn rẹ dáadáa.—Òwe 27:23.
Ó dájú pé ìlànà tó wà nínú Jémíìsì 1:19 kan àwọn tó ń gbani nímọ̀ràn. Jémíìsì sọ pé: “Ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára láti gbọ́rọ̀, kí wọ́n lọ́ra láti sọ̀rọ̀, kí wọ́n má sì tètè máa bínú.” Alàgbà kan lè ronú pé òun ti mọ gbogbo nǹkan tó yẹ kóun mọ̀ nípa ẹnì kan, àmọ́ ṣé òótọ́ ni? Òwe 18:13 rán wa létí pé: “Tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀rọ̀ láì tíì gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀, ìwà òmùgọ̀ ni, ó sì ń kó ìtìjú báni.” Ohun tó dáa jù ni pé ká gbọ́rọ̀ lẹ́nu onítọ̀hún fúnra ẹ̀. Ìyẹn sì máa gba pé ká fetí sílẹ̀ dáadáa ká tó mọ ohun tá a máa sọ. Alàgbà náà lè bi ẹni náà láwọn ìbéèrè bíi: “Báwo ni nǹkan ṣe ń lọ sí?” “Ọ̀nà wo ni mo lè gbà ràn yín lọ́wọ́?” Táwọn alàgbà bá ń fara balẹ̀ wádìí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ará kí wọ́n tó lọ gbà wọ́n nímọ̀ràn, á rọrùn fún wọn láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lọ́wọ́, kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí. Kéèyàn gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn tó máa ṣe wọ́n láǹfààní kọjá ká kàn ka àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan tàbí ká fún wọn láwọn àbá kan. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa gbọ́dọ̀ rí i pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn, a lóye àwọn àti pé a fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. w22.02 17 ¶14-15