June
Thursday, June 1
Opó kan tó jẹ́ aláìní wá, ó sì fi ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré gan-an síbẹ̀.—Máàkù 12:42.
Nǹkan ò rọrùn fún opó náà, kódà tipátipá ló fi ń rówó gbọ́ bùkátà ara ẹ̀. Síbẹ̀, ó rọra lọ síbi ọ̀kan lára àwọn àpótí náà, ó sì sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì sínú ẹ̀. Bóyá lowó náà tiẹ̀ dún rárá bó ṣe sọ ọ́ sínú ẹ̀. Jésù mọ̀ pé owó lẹ́pítónì méjì tí ìníyelórí ẹ̀ kéré jù nígbà yẹn ló sọ sí i. Kódà, owó yẹn ò lè ra ológoṣẹ́ kan, ìyẹn ẹyẹ tí ìníyelórí ẹ̀ kéré jù nígbà yẹn. Ohun tí opó yẹn ṣe wú Jésù lórí gan-an. Torí náà, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Ohun tí opó aláìní yìí fi sílẹ̀ ju ti gbogbo àwọn yòókù” lọ. Ó wá fi kún un pé: “Gbogbo wọn [pàápàá àwọn olówó] fi síbẹ̀ látinú àjẹṣẹ́kù wọn, àmọ́ òun, láìka pé kò ní lọ́wọ́, ó fi gbogbo ohun tó ní síbẹ̀, gbogbo ohun tó ní láti gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró.” (Máàkù 12:43, 44) Ṣe ni opó náà ń fira ẹ̀ sọ́wọ́ Jèhófà bó ṣe fi gbogbo owó tó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ ẹ̀ sínú àpótí lọ́jọ́ yẹn.—Sm. 26:3. w21.04 6 ¶17-18
Friday, June 2
Ẹ wò ó! ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù.—Ìṣe 5:28.
Ọwọ́ gidi ni Jésù fi mú iṣẹ́ ìwàásù nígbà tó wà láyé, ohun tó sì fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ṣe náà nìyẹn. (Jòh. 4:35, 36) Nígbà tí Jésù ṣì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, tìtaratìtara làwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ fi wàásù. (Lúùkù 10:1, 5-11, 17) Àmọ́ lẹ́yìn táwọn alátakò mú Jésù tí wọ́n sì pa á, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ dẹwọ́ fúngbà díẹ̀. (Jòh. 16:32) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Lẹ́yìn tí Jésù pa dà sọ́run, àwọn ọmọ ẹ̀yìn fìtara wàásù débi táwọn alátakò fi sọ ohun tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní. Jésù ló darí iṣẹ́ ìwàásù táwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe, Jèhófà sì bù kún wọn débi pé ọ̀pọ̀ èèyàn dara pọ̀ mọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 S.K., nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ló ṣèrìbọmi. (Ìṣe 2:41) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn ọmọlẹ́yìn ń pọ̀ sí i. (Ìṣe 6:7) Síbẹ̀, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù náà máa dé ọ̀pọ̀ ibi láyé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa di ọmọlẹ́yìn.—Jòh. 14:12; Ìṣe 1:8. w21.05 14 ¶1-2
Saturday, June 3
Aláyọ̀ ni ẹni tí kò rí ohunkóhun tó máa mú kó kọsẹ̀ nínú mi.—Mát. 11:6.
Ṣé o rántí bí inú ẹ ṣe dùn tó nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Lọ́kàn ẹ, ó dá ẹ lójú pé gbogbo èèyàn ló máa nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ yìí. O gbà pé òtítọ́ Bíbélì máa jẹ́ kí ìgbésí ayé wọn nítumọ̀ báyìí, á sì jẹ́ kí wọ́n ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. (Sm. 119:105) Torí náà, tọkàntara lo fi ń sọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ. Àmọ́ ó yà ẹ́ lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ni ò mọyì ohun tó ò ń sọ fún wọn. Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu bí ọ̀pọ̀ èèyàn ò bá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tá à ń wàásù. Ó ṣe tán, nígbà tí Jésù wà láyé, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tó fi hàn pé Ọlọ́run ló fún un lágbára, tó sì ń tì í lẹ́yìn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò tẹ́tí sí i. Bí àpẹẹrẹ, ojú gbogbo èèyàn ló ṣe nígbà tí Jésù jí Lásárù dìde, síbẹ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù ò gbà pé òun ni Mèsáyà. Kódà, ṣe ni wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa pa Jésù àti Lásárù!—Jòh. 11:47, 48, 53; 12:9-11. w21.05 2 ¶1-2
Sunday, June 4
Ẹ má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀, àmọ́ ẹ jẹ́ ká máa gba ara wa níyànjú.—Héb. 10:25.
Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa lọ sípàdé déédéé. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí ìṣírí gbà, wàá sì túbọ̀ mọ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó o lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, yálà wọ́n kéré sí ẹ lọ́jọ́ orí tàbí wọ́n dàgbà jù ẹ́ lọ, tàbí kó jẹ́ pé àṣà wọn yàtọ̀ sí tìẹ. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn àgbà la ti ń rí ọgbọ́n.” (Jóòbù 12:12) Kódà, àwọn àgbàlagbà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ọmọdé tó wà nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì kéré gan-an lọ́jọ́ orí sí Jónátánì, síbẹ̀ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ni wọ́n. (1 Sám. 18:1) Àwọn méjèèjì sì ran ara wọn lọ́wọ́ láti máa sin Jèhófà kódà lójú ìṣòro. (1 Sám. 23:16-18) Arábìnrin Irina tó jẹ́ pé òun nìkan ni Ẹlẹ́rìí nínú ìdílé rẹ̀ sọ pé: “Àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin lè dà bí òbí tàbí ọmọ ìyá wa. Jèhófà sì lè lò wọ́n láti ràn wá lọ́wọ́.” Àwọn ará ṣe tán láti dúró tì ẹ́, kí wọ́n sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ sọ ohun tó ò ń bá yí fún wọn kí wọ́n tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. w21.06 10-11 ¶9-11
Monday, June 5
Bẹ́ẹ̀ náà ni Baba mi ọ̀run máa ṣe sí yín tí kálukú yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ látọkàn wá.—Mát. 18:35.
Jésù sọ àkàwé kan fún àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ nípa ọba kan àti ẹrú rẹ̀. Ẹrú yìí jẹ ọba náà ní gbèsè tí ò lè san láéláé, àmọ́ ọba náà fagi lé gbèsè ẹ̀. Nígbà tó yá, ẹrú yìí rí ẹrú míì tó jẹ ẹ́ ní gbèsè owó díẹ̀, ó sì kọ̀ láti dárí jì í. Inú bí ọba náà, ó sì ju ẹrú burúkú náà sẹ́wọ̀n. Ẹrú yìí jìyà ohun tó ṣe, àmọ́ ohun tó ṣe yẹn tún kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn míì. Lọ́nà wo? Lákọ̀ọ́kọ́, ó fìyà jẹ ẹrú ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ nígbà tó “ní kí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n títí ó fi máa san gbèsè tó jẹ pa dà.” Ìkejì, ó dun àwọn ẹrú yòókù nígbà tí wọ́n rí ohun tó ṣe. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú rí ohun tó ṣẹlẹ̀, inú wọn bà jẹ́ gan-an.” (Mát. 18:30, 31) Lọ́nà kan náà, ohun tá a bá ṣe lè ṣàkóbá fáwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá, tá ò sì dárí jì í, kí ló lè ṣẹlẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, a máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹni náà torí pé a ò dárí jì í, a ò sì fìfẹ́ hàn sí i. Ìkejì, inú àwọn tó wà nínú ìjọ ò ní dùn tí wọ́n bá rí i pé àárín àwa àti ẹni náà ò gún. w21.06 22 ¶11-12
Tuesday, June 6
Ó máa run àwọn tó ń run ayé.—Ìfi. 11:18.
Jèhófà dá wa ní àwòrán rẹ̀, àmọ́ Sátánì máa ń fẹ́ ká ṣèṣekúṣe ká sì máa hùwàkiwà. Nígbà tí Ọlọ́run “rí i pé ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an” nígbà ayé Nóà, “ó dun Jèhófà pé òun dá èèyàn sáyé, ọkàn rẹ̀ sì bà jẹ́.” (Jẹ́n. 6:5, 6, 11) Ṣé nǹkan ti wá yí pa dà látìgbà yẹn? Rárá o! Ẹ wo bínú Èṣù ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí i táwọn èèyàn ń lọ́wọ́ nínú onírúurú ìṣekúṣe, títí kan bí àwọn ọkùnrin ṣe ń bá àwọn ọkùnrin lò pọ̀ àti bí àwọn obìnrin ṣe ń bá àwọn obìnrin lò pọ̀! (Éfé. 4:18, 19) Inú Sátánì tún máa ń dùn yàtọ̀ tó bá lè mú kí ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo. Nínú ayé Sátánì, yàtọ̀ sí pé èèyàn ń “jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀,” wọ́n tún ń ba ilẹ̀ ayé jẹ́, wọ́n sì ń ṣèpalára fún àwọn ẹranko tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wa. (Oníw. 8:9; Jẹ́n. 1:28) Kí nìyẹn ti wá yọrí sí? Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ohun táwọn èèyàn ń ṣe lónìí lè mú kí onírúurú ẹ̀dá alààyè tó lé ní mílíọ̀nù kan pòórá pátápátá lórí ilẹ̀ ayé láàárín ọdún mélòó kan sígbà tá a wà yìí. w21.07 12 ¶13-14
Wednesday, June 7
[Jèhófà] máa dárí jini fàlàlà.—Àìsá. 55:7.
Àwọn kan lára àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣì máa ń dára wọn lẹ́bi torí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá ṣẹ́yìn. Ọkàn wọn tó ṣì ń dá wọn lẹ́bi ń mú kí wọ́n rò pé Jèhófà ò lè dárí ji àwọn láé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ronú pìwà dà tí wọn ò sì dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe rí fún ìwọ náà nìyẹn, mọ̀ dájú pé Ọlọ́run máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹ, á sì mú kó o borí èrò náà, kí o lè máa fi ayọ̀ sin Jèhófà pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Èyí ṣeé ṣe torí pé ‘ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.’ (1 Jòh. 1:7) Tí àwọn àṣìṣe ẹ bá ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ, rántí pé Jèhófà ṣe tán láti dárí jì ẹ́ tó o bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Wo ohun tí onísáàmù náà Dáfídì sọ tó fi hàn pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ló ń mú kí Ọlọ́run dárí jini. Ó sọ pé: “Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ṣe ga. Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.”—Sm. 103:11, 12. w21.11 5-6 ¶12-13
Thursday, June 8
Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, wọ́n sì pè é ní aláyọ̀; ọkọ rẹ̀ dìde, ó sì yìn ín.—Òwe 31:28.
Àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ máa bọlá fún ìyàwó wọn. (1 Pét. 3:7) Tá a bá sọ pé a bọlá fún ẹnì kan, ó túmọ̀ sí pé a ka ẹni náà sí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, a sì bọ̀wọ̀ fún un. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ kan lè bọlá fún ìyàwó ẹ̀ tó bá ń pọ́n ọn lé, tó sì ń buyì kún un. Kì í retí pé kó ṣe ju agbára ẹ̀ lọ bẹ́ẹ̀ ni kì í fi wé àwọn obìnrin míì. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá ń fi ìyàwó ẹ̀ wé àwọn obìnrin míì? Ọkọ Arábìnrin Rosa kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì máa ń fi í wé àwọn obìnrin míì. Ọ̀rọ̀ tó máa ń sọ ti jẹ́ kí Rosa ronú pé òun ò wúlò àti pé kò sẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ òun. Arábìnrin náà sọ pé: “Mo máa ń fẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi.” Bó ti wù kó rí, àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni máa ń bọlá fún ìyàwó wọn. Wọ́n mọ̀ pé ọwọ́ tí àwọn bá fi mú ìyàwó àwọn ló máa pinnu bí àjọṣe àárín àwọn pẹ̀lú ìyàwó wọn ṣe máa rí àti bí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà ṣe máa rí. Ọkọ tó ń bọlá fún ìyàwó ẹ̀ máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ dáadáa fáwọn míì, ó máa ń gbóríyìn fún un, ó máa ń sọ fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, òun sì mọyì rẹ̀. w21.07 22 ¶7-8
Friday, June 9
Màá dúró de Ọlọ́run.—Míkà 7:7.
Ṣé ó máa ń dùn ẹ́ tí ẹrù kan tó ò ń retí lójú méjèèjì ò bá dé lásìkò? Ká wá sọ pé wọ́n ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ fún ẹ, ó dájú pé wàá mú sùúrù títí ẹrù náà á fi dé. Ìlànà Bíbélì kan tó jẹ́ ká rídìí tó fi yẹ ká máa mú sùúrù wà nínú Òwe 13:11. Ó sọ pé: “Ọrọ̀ tí èèyàn fi ìkánjú kó jọ kì í pẹ́ tán, àmọ́ ọrọ̀ tí èèyàn ń kó jọ díẹ̀díẹ̀ á máa pọ̀ sí i.” Ẹ̀kọ́ wo lèyí kọ́ wa? Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé tá a bá ń fara balẹ̀, tá a sì ń mú sùúrù, àá ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Òwe 4:18 sọ pé: “Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ àárọ̀ tó ń mọ́lẹ̀ sí i títí di ọ̀sán gangan.” Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà ń mú káwọn èèyàn rẹ̀ mọ ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe. Àmọ́, a tún lè lo ẹsẹ Bíbélì yìí láti ṣàpèjúwe bí Kristẹni kan ṣe ń ṣe ìyípadà nígbèésí ayé ẹ̀, tó sì túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà. Gbogbo wa la mọ̀ pé ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè fàwọn ìwà àtijọ́ sílẹ̀ kó sì sún mọ́ Jèhófà. w21.08 8 ¶1, 3-4
Saturday, June 10
Èmi nìyí! Rán mi!—Àìsá. 6:8.
Iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run túbọ̀ ń pọ̀ sí i bí ayé yìí ṣe ń lọ sópin. (Mát. 24:14; Lúùkù 10:2; 1 Pét. 5:2) Gbogbo wa ló wù pé ká ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ọ̀pọ̀ sì ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ó wu àwọn kan láti di aṣáájú-ọ̀nà, ó wu àwọn míì láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń kọ́lé ètò Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ń sapá kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. (1 Tím. 3:1, 8) Ẹ wo bínú Jèhófà ṣe ń dùn tó bó ṣe ń rí ẹ̀mí tó dáa táwọn èèyàn ẹ̀ ní! (Sm. 110:3) Ṣé o ò ti máa rẹ̀wẹ̀sì torí pé o ò tíì ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù ẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, sọ bó ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà. (Sm. 37:5-7) Bákan náà, o lè ní kí àwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn sọ ohun tó o lè ṣe kí ọwọ́ ẹ lè tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù ẹ́, kó o sì rí i pé o fi ìmọ̀ràn wọn sílò. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ lè tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn náà. w21.08 20 ¶1; 21 ¶4
Sunday, June 11
Jèhófà. . .kòní kọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.—Sm. 37:28.
Opó ni Ánà tó jẹ́ wòlíì obìnrin, ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84), síbẹ̀ “kì í pa wíwá sí tẹ́ńpìlì jẹ.” Jèhófà mọyì bó ṣe máa ń “wá sí tẹ́ńpìlì déédéé,” ó sì fún un láǹfààní láti rí Jésù nígbà tó wà ní kékeré. (Lúùkù 2:36-38) Lónìí, a ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbàlagbà tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà tí wọ́n sì jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fáwọn ọ̀dọ́. A máa kẹ́kọ̀ọ́ gan-an lára wọn tá a bá fi sùúrù bi wọ́n láwọn ìbéèrè táá jẹ́ kí wọ́n sọ tọkàn wọn, tá a sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn bí wọ́n ṣe ń sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tí wọ́n ti ní nínú ètò Ọlọ́run. Ipa ribiribi làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó jẹ́ àgbàlagbà ń kó nínú ètò Jèhófà. Wọ́n ti rí onírúurú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bù kún ètò rẹ̀ àti bó ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbèésí ayé wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe tí wọ́n ṣe. Torí náà, gbà pé àwọn àgbàlagbà jẹ́ “orísun ọgbọ́n,” kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. (Òwe 18:4) Tó o bá sún mọ́ wọn, ó dájú pé ìgbàgbọ́ rẹ á túbọ̀ lágbára. w21.09 3 ¶4; 4 ¶7-8; 5 ¶11, 13
Monday, June 12
Ẹni tó kéré máa di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré sì máa di orílẹ̀-èdè alágbára.—Àìsá. 60:22.
Bí Àìsáyà ṣe sọ, àwa èèyàn Jèhófà ń rí “wàrà àwọn orílẹ̀-èdè” mu. (Àìsá. 60:5, 16) Ẹ̀bùn tó yàtọ̀ síra táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń wá sínú òtítọ́ yìí ní ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa wàásù ká sì máa tẹ àwọn ìwé wa. A ti ń wàásù ní orílẹ̀-èdè ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ogójì (240), a sì ń tẹ àwọn ìwé wa ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000). Bí Jèhófà ṣe ń mi gbogbo orílẹ̀-èdè ń mú kó pọn dandan fáwọn èèyàn láti ṣèpinnu. Ṣé wọ́n máa fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run àbí wọ́n máa gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìjọba ayé yìí? Oníkálukú ló máa pinnu ohun tó fẹ́ ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pa gbogbo òfin ìlú tá à ń gbé mọ́, síbẹ̀ a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀. (Róòmù 13:1-7) A mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ni ojútùú sí ìṣòro aráyé. Ìjọba yẹn kì í sì í ṣe apá kan ayé yìí.—Jòh. 18:36, 37. w21.09 17-18 ¶13-14
Tuesday, June 13
Ẹ tú ọkàn yín jáde níwájú rẹ̀.—Sm. 62:8.
Tí ẹni tá a nífẹ̀ẹ́ bá fi Jèhófà sílẹ̀, ó ṣe pàtàkì kó o máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tìẹ àti tàwọn tó kù nínú ìdílé ẹ túbọ̀ lágbára. Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó ò ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀, tó o sì ń lọ sípàdé déédéé. Joanna tí bàbá ẹ̀ àti ẹ̀gbọ́n ẹ̀ fi òtítọ́ sílẹ̀ sọ pé: “Ara máa ń tù mí tí mo bá kà nípa àwọn tí Bíbélì mẹ́nu kàn, bí Ábígẹ́lì, Ẹ́sítà, Jóòbù, Jósẹ́fù àti Jésù. Àpẹẹrẹ wọn máa ń fún mi níṣìírí, ó sì máa ń jẹ́ kí n ní èrò tó tọ́ táá jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀.” Ìgbàkigbà tó o bá tún ní ìdààmú ọkàn, má ṣe dákẹ́ àdúrà. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fi ojú tó fi ń wo nǹkan wò ó àti pé kó ‘fún ẹ ní ìjìnlẹ̀ òye, kó sì kọ́ ẹ ní ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.’ (Sm. 32:6-8) Òótọ́ ni pé ó lè ṣòro fún ẹ láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ gẹ́lẹ́ fún Jèhófà. Àmọ́ jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ọ̀rọ̀ ẹ yé e, ó mọ bọ́rọ̀ náà ṣe ń dùn ẹ́ tó, ó sì fẹ́ kó o sọ bó ṣe rí lára ẹ fún òun.—Ẹ́kís. 34:6; Sm. 62:7. w21.09 28 ¶9-10
Wednesday, June 14
Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà. Ẹ fetí sí i.—Mát. 17:5.
Lẹ́yìn Ìrékọjá ọdún 32 S.K., àpọ́sítélì Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù rí ìran kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Nígbà tí wọ́n wà ní apá kan Òkè Hámónì tó ga fíofío, Jèhófà yí Jésù pa dà di ológo níwájú wọn. “Ojú rẹ̀ tàn bí oòrùn, aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sì tàn yòò bí ìmọ́lẹ̀.” (Mát. 17:1-4) Àwọn àpọ́sítélì gbọ́ tí Jèhófà sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà. Ẹ fetí sí i.” Ohun táwọn àpọ́sítélì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fi ìgbésí ayé wọn ṣe fi hàn pé wọ́n tẹ́tí sí Jésù lóòótọ́. Ohun tó sì yẹ káwa náà ṣe nìyẹn. A dúpẹ́ pé Jèhófà ń fìfẹ́ darí wa nípasẹ̀ Jésù Kristi tó jẹ́ “orí ìjọ.” (Éfé. 5:23) Bíi ti àpọ́sítélì Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa “fetí sí” Jésù. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa gba ọ̀pọ̀ ìbùkún nísinsìnyí, àá sì ní ayọ̀ tí kò lópin lọ́jọ́ iwájú. w21.12 22 ¶1; 27 ¶19
Thursday, June 15
Mi ò ní bá ọ wí kọjá ààlà.—Jer. 30:11.
Arákùnrin kan ní Kọ́ríńtì ń ṣe ìṣekúṣe pẹ̀lú ìyàwó bàbá ẹ̀. Torí náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé kí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Ìwà ìbàjẹ́ tí ọkùnrin yìí hù ti ń ṣàkóbá fún àwọn tó wà nínú ìjọ, àwọn kan ò sì rí ohun tó burú nínú ohun tí ọkùnrin náà ṣe. (1 Kọ́r. 5:1, 2, 13) Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù gbọ́ pé ọkùnrin náà ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn alàgbà yẹn pé: “Kí ẹ dárí jì í tinútinú, kí ẹ sì tù ú nínú.” Ẹ kíyè sí ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Kí ìbànújẹ́ tó pọ̀ lápọ̀jù má bàa bò ó mọ́lẹ̀.” Àánú ọkùnrin yẹn ṣe Pọ́ọ̀lù. Kò fẹ́ kí ìbànújẹ́ bo ọkùnrin náà mọ́lẹ̀, kí ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀ sì pọ̀ débi táá fi ro ara ẹ̀ pin pé Ọlọ́run ò lè dárí ji òun mọ́. (2 Kọ́r. 2:5-8, 11) Bíi ti Jèhófà, ó máa ń wu àwọn alàgbà láti fàánú hàn. Tí wọ́n bá rí i pé ó pọn dandan kí wọ́n fún ẹnì kan ní ìbáwí tó le, wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, wọ́n ṣì máa ń fàánú hàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Tó bá yẹ káwọn alàgbà bá oníwà àìtọ́ kan wí, àmọ́ tí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀, àánú kọ́ ni wọ́n fi hàn yẹn, ṣe ni wọ́n gbàgbàkugbà láyè. w21.10 11-12 ¶12-15
Friday, June 16
O ò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san tàbí kí o di èèyàn sínú.—Léf. 19:18.
Táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá, ó dà bí ìgbà tí nǹkan gé wa lọ́wọ́. Ojú ibi tí nǹkan ti gé wa lè kéré tàbí kó tóbi. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀bẹ lè géni lọ́wọ́ fẹ́rẹ́. Ó máa ń dunni gan-an, àmọ́ ká tó rí ọjọ́ mélòó kan, á ti sàn, a sì lè má rí ojú àpá náà mọ́. Lọ́nà kan náà, ohun táwọn èèyàn ṣe fún wa lè má tó nǹkan. Ọ̀rẹ́ wa lè sọ tàbí ṣe ohun kan tó dùn wá, àmọ́ a máa ń tètè dárí jì í. Ṣùgbọ́n ká sọ pé ojú ibi tí ọ̀bẹ ti gé wa tóbi, ó lè gba pé kí dókítà bá wa rán an, kó sì fi báńdééjì wé e. Tá a bá wá ń fọwọ́ tẹ ojú ọgbẹ́ náà, àá ṣe ara wa léṣe. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa rí fún ẹnì kan tí wọ́n ṣẹ̀, tí nǹkan náà sì dùn ún gan-an. Tó bá jẹ́ pé ohun tí wọ́n ṣe fún un ló ń rò ṣáá àti bí ọ̀rọ̀ náà ṣe dùn ún tó, ńṣe lá kàn máa ba ara ẹ̀ nínú jẹ́. Ẹ ò rí i pé ó dáa gan-an ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. w21.12 12 ¶15
Saturday, June 17
Kí ló dé tí o fi ń dá arákùnrin rẹ lẹ́jọ́?—Róòmù 14:10.
Ká sọ pé alàgbà kan kọminú sí bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan ṣe ń múra. Alàgbà náà lè bi ara ẹ̀ pé, ‘Ṣé Bíbélì sọ nǹkan kan tó jẹ́ kí n mọ̀ pé bí ẹni yẹn ṣe ń múra ò dáa?’ Torí pé alàgbà náà ò ní fẹ́ fi èrò tiẹ̀ gba ẹni náà nímọ̀ràn, ó lè bi alàgbà kan tàbí akéde míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ pé kí ni wọ́n rò nípa ẹ̀. Wọ́n wá lè jọ wo ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà wá nípa bó ṣe yẹ ká máa múra. (1 Tím. 2:9, 10) Pọ́ọ̀lù sọ àwọn ìlànà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé, ó ní ìmúra àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ bójú mu, kó mọ níwọ̀n, kó sì fi hàn pé a láròjinlẹ̀. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò ṣòfin máṣu mátọ̀ nípa ohun tó yẹ ká máa wọ̀ àtohun tí kò yẹ ká wọ̀. Ó mọ̀ pé àwọn ará lè wọ ohun tó bá wù wọ́n, tí ohun tí wọ́n wọ̀ ò bá ṣáà ti lòdì sí ìlànà Bíbélì. Torí náà, táwọn alàgbà bá fẹ́ pinnu bóyá káwọn lọ gba ẹnì kan nímọ̀ràn, ó yẹ káwọn alàgbà wò ó bóyá ìmúra ẹni náà mọ níwọ̀n, ó sì bójú mu. Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn Kristẹni méjì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lè ṣèpinnu tó yàtọ̀ síra, ìyẹn ò sì sọ pé ọ̀kan dáa ju èkejì lọ. Torí náà, kò yẹ ká máa fipá mú àwọn ará pé kí wọ́n ṣe ohun tá a rò pé ó bójú mu. w22.02 16 ¶9-10
Sunday, June 18
Kí ìfẹ́ tí ẹ ní sí ara yín má yẹ̀, kí ẹ sì máa ṣàánú ara yín.—Sek. 7:9.
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ara wa. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára wọn. Ẹ kíyè sí ohun tí àwọn ẹsẹ Bíbélì inú ìwé Òwe yìí sọ nípa wọn: “Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìṣòtítọ́ fi ọ́ sílẹ̀. . . . Nígbà náà, wàá rí ojú rere àti òye tó jinlẹ̀ gan-an lójú Ọlọ́run àti èèyàn.” “Ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ń ṣe ara rẹ̀ láǹfààní.” “Ẹni tó bá ń wá òdodo àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ yóò rí ìyè.” (Òwe 3:3, 4; 11:17, àlàyé ìsàlẹ̀; 21:21) Àwọn ẹsẹ Bíbélì inú ìwé Òwe yìí mẹ́nu kan nǹkan mẹ́ta tó fi yẹ ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn. Àkọ́kọ́, tá a bá ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn, Ọlọ́run máa mọyì wa. Ìkejì, tá a bá ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn, a máa ṣe ara wa láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, àjọṣe tó wà láàárín àwọn tá a jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ máa wà pẹ́ títí. Ìkẹta, tá ò bá jẹ́ kó sú wa láti máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn, a máa gba èrè tó pọ̀ lọ́jọ́ iwájú títí kan ìyè àìnípẹ̀kun. Ká sòótọ́, ó yẹ káwọn nǹkan yìí mú ká máa fi ìmọ̀ràn Jèhófà yìí sọ́kàn pé: “Kí ìfẹ́ tí ẹ ní sí ara yín má yẹ̀, kí ẹ sì máa ṣàánú ara yín.” w21.11 8 ¶1-2
Monday, June 19
Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.—Lúùkù 17:5.
Tó o bá rí i pé àwọn ìṣòro tó o ní báyìí àbí àwọn èyí tó o ti dojú kọ sẹ́yìn fi hàn pé ìgbàgbọ́ ẹ ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára, má ṣe jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ. Lo àǹfààní yìí láti ṣe nǹkan tó máa jẹ́ kígbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára. Máa gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà pàápàá tó o bá dojú kọ ìṣòro. Máa fi sọ́kàn pé ó lè jẹ́ àwọn ìdílé ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ nínú ìjọ ni Jèhófà máa lò láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá jẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o ṣe ń fara da àwọn ìṣòro tó o ní báyìí, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí àwọn àdánwò tó o máa dojú kọ lọ́jọ́ iwájú. Lóòótọ́, ìgbà kan wà tí Jésù sọ pé ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ò lágbára tó, àmọ́ ó dá a lójú pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn àdánwò wọn lọ́jọ́ iwájú. (Jòh. 14:1; 16:33) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún dá Jésù lójú pé ìgbàgbọ́ tó lágbára ló máa mú káwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn la ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ já. (Ìfi. 7:9, 14) Ìwọ náà máa wà lára wọn tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ní ìgbàgbọ́, tó o sì ń jẹ́ kígbàgbọ́ ẹ máa lágbára sí i báyìí!—Héb. 10:39. w21.11 25 ¶18-19
Tuesday, June 20
Áńgẹ́lì Jèhófà pàgọ́ yí àwọn tó bẹ̀rù Rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.—Sm. 34:7.
A ò retí pé kí Jèhófà dá wa nídè lọ́nà ìyanu lónìí, àmọ́ ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé ẹnikẹ́ni tó gbẹ́kẹ̀ lé e. Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, gbogbo wa pátá la máa fi hàn bóyá ó dá wa lójú tàbí kò dá wa lójú pé Jèhófà lágbára láti dáàbò bò wá. Nígbà tí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tí Bíbélì pè ní Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run, ṣe ló máa dà bíi pé wẹ́rẹ́ ni wọ́n á pa wá run. Lásìkò yẹn, ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà lágbára láti dá wa nídè, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀. Lójú àwọn orílẹ̀-èdè yẹn, a máa dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ tó lè dáàbò bò wọ́n. (Ìsík. 38:10-12) Ó ṣe tán, a ò níbọn tàbí àwọn nǹkan ìjà ogun míì, bẹ́ẹ̀ la ò sì kọ́ṣẹ́ ogun. Torí náà, àwọn orílẹ̀-èdè máa ronú pé ṣìnkún báyìí lọwọ́ àwọn á tẹ̀ wá. Ó mà ṣe o, àwọn orílẹ̀-èdè ò ní rí ohun táà ń fojú ìgbàgbọ́ wa rí, ìyẹn àwọn ọmọ ogun ọ̀run tí wọ́n pagbo yí wa ká, tí wọ́n sì ṣe tán láti gbèjà wa. Kí nìdí tí wọn ò fi rí àwọn ọmọ ogun ọ̀run yẹn? Ìdí ni pé wọn ò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Ó dájú pé wọ́n á kan ìdin nínú iyọ̀ nígbà tí àwọn ọmọ ogun ọ̀run bá gbèjà wa!—Ìfi. 19:11, 14, 15. w22.01 6 ¶12-13
Wednesday, June 21
Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará.—1 Pét. 2:17.
Gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ṣeyebíye lójú Jèhófà, torí náà, ó yẹ kí wọ́n ṣeyebíye lójú tiwa náà. Torí náà, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti dáàbò bò wọ́n ká sì bójú tó wọn. Tá a bá rí i pé a ṣẹ ẹnì kan, kò yẹ ká gbójú fò ó ká sì ronú pé nǹkan ti máa ń ká a lára jù. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ fi máa ń tètè dun àwọn kan? Àwọn ará wa kan máa ń ronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan bóyá torí bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà. Àwọn míì ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kò sì rọrùn fún wọn láti gbójú fo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ará. Èyí ó wù kó jẹ́, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti rí i pé àlàáfíà wà láàárín wa. Bákan náà, ẹni tí ọ̀rọ̀ tètè máa ń dùn gbọ́dọ̀ mọ̀ pé kùdìẹ̀-kudiẹ kan ni òun ní, òun sì gbọ́dọ̀ sapá gan-an láti borí ẹ̀. Ó ṣe pàtàkì kó ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá fẹ́ kí ọkàn òun balẹ̀ kóun sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará. w21.06 21 ¶7
Thursday, June 22
Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́.—Sm. 145:18.
Jésù máa ń bá wa kẹ́dùn. Inú wa dùn pé a ní ẹni tó lè bá wa kẹ́dùn tá a bá wà nínú ìṣòro torí pé òun náà ti kojú irú ìṣòro tá a ní. Ṣẹ́ ẹ mọ ẹni náà? Jésù ni. Ó mọ bó ṣe máa ń rí téèyàn ò bá lókun mọ́ tó sì nílò ìrànlọ́wọ́. Ó mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa, ó sì máa ń rí i dájú pé a rí ìrànlọ́wọ́ tá a nílò “ní àkókò tó tọ́.” (Héb. 4:15, 16) Jésù gbà kí áńgẹ́lì tí Jèhófà rán sí i nínú ọgbà Gẹ́tísémánì ran òun lọ́wọ́. Torí náà, ó yẹ káwa náà gba ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń fún wa nípasẹ̀ àwọn ìwé wa, fídíò, àsọyé àti ọ̀rọ̀ ìṣírí tí alàgbà tàbí ọ̀rẹ́ wa kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ sọ fún wa. (Lúùkù 22:39-44) Jèhófà máa fún ẹ ní “àlàáfíà” rẹ̀, á sì fún ẹ lókun. Tá a bá gbàdúrà, a máa ní “àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye.”—Fílí. 4:6, 7. w22.01 18-19 ¶17-19
Friday, June 23
Wọ́n ń fi àwọn àṣẹ tí àwọn àpọ́sítélì . . . ti pinnu lé lórí jíṣẹ́ fún wọn.—Ìṣe 16:4.
Jèhófà máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo. Àmọ́, ó lè ṣòro fún wa láti fọkàn tán àwọn tí Jèhófà ní kó máa ṣàbójútó wa. A lè máa rò ó pé, ṣé ohun tí Jèhófà ní káwọn tó ń ṣàbójútó wa nínú ètò rẹ̀ máa ṣe ni wọ́n ń ṣe, àbí ohun tó wù wọ́n? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé a ò lè fọkàn tán Jèhófà táò bá fọkàn tán àwọn tó ní kó máa ṣàbójútó nínú ètò rẹ̀ torí pé Jèhófà ti fọkàn tán wọn. Lónìí, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ni Jèhófà ń lò láti darí àwa èèyàn ẹ̀. (Mát. 24:45) Bíi ti ìgbìmọ̀ olùdarí nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, ẹrú yìí ló ń ṣàbójútó àwa èèyàn Ọlọ́run kárí ayé, wọ́n sì ń fún àwọn alàgbà ní ìtọ́sọ́nà. Àwọn alàgbà á sì rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà náà nínú ìjọ. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run àti tàwọn alàgbà ìjọ, ìyẹn á fi hàn pé a fọkàn tán Jèhófà pé ó máa ń ṣe ohun tó tọ́. w22.02 4 ¶7-8
Saturday, June 24
Ẹ má ṣe jẹ́ kí a jáwọ́ nínú ṣíṣe rere.—Gál. 6:9.
Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní bá a ṣe jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn sì ń múnú wa dùn gan-an. Inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá ran “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” lọ́wọ́ débi tí wọ́n fi ṣèrìbọmi. (Ìṣe 13:48) Ṣe lọ̀rọ̀ tiwa náà máa dà bíi ti Jésù tó “yọ̀ gidigidi nínú ẹ̀mí mímọ́” nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ dé látibi tí wọ́n ti lọ wàásù. (Lúùkù 10:1, 17, 21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún rọ Tímótì pé: “Máa kíyè sí ara rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ.” Pọ́ọ̀lù wá fi kún un pé: “Tí o bá ń ṣe é, wàá lè gba ara rẹ àti àwọn tó ń fetí sí ọ là.” (1 Tím. 4:16) Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà niṣẹ́ ìwàásù. Torí náà, a máa ń kíyè sí ara wa torí pé ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ni wá. A máa ń ṣe ohun tó ń fògo fún Jèhófà tí ò sì ní ta ko ìhìn rere tá à ń wàásù rẹ̀. (Fílí. 1:27) A máa fi hàn pé à ń ‘kíyè sí ẹ̀kọ́ wa’ tá a bá ń múra òde ẹ̀rí sílẹ̀ dáadáa, tá a sì ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká tó lọ wàásù fáwọn èèyàn. w21.10 24 ¶1-2
Sunday, June 25
Ẹ fi ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.—Kól. 3:10.
Tẹ́nì kan bá ní “ìwà tuntun,” á máa ronú, á sì máa hùwà lọ́nà tó bá ti Jèhófà mu. Ẹnì kan lè fi ìwà tuntun wọ ara ẹ̀ láṣọ tó bá ń fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí ìwà àti ìṣe òun. Bí àpẹẹrẹ, ẹni náà máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn ẹ̀. (Mát. 22:36-39) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń láyọ̀ kódà, tí ìṣòro bá ń bá a fínra. (Jém. 1:2-4) Èèyàn àlàáfíà ni. (Mát. 5:9) Ó máa ń ní sùúrù, ó sì jẹ́ onínúure. (Kól. 3:13) Ó nífẹ̀ẹ́ ohun tó dáa, ó sì máa ń ṣe rere. (Lúùkù 6:35) Ìwà rẹ̀ máa ń fi hàn pé ó nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run. (Jém. 2:18) Kì í bínú sódì tí wọ́n bá kàn án lábùkù, ó sì máa ń kó ara rẹ̀ níjàánu tó bá kojú ìdẹwò. (1 Kọ́r. 9:25, 27; Títù 3:2) Ká tó lè fi ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ, a gbọ́dọ̀ ní gbogbo ìwà tó wà nínú Gálátíà 5:22, 23 àtàwọn ìwà tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì míì. w22.03 8-9 ¶3-4
Monday, June 26
Ẹ máa fara wé mi.—1 Kọ́r. 11:1.
Ẹ̀yin alàgbà máa fi hàn pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹ́ ẹ bá ń lo gbogbo àǹfààní tó bá yọ láti wàásù fáwọn èèyàn, kì í ṣe tẹ́ ẹ bá ń wàásù láti ilé dé ilé nìkan. (Éfé. 6:14, 15) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹ̀yin alàgbà tún lè lo àkókò tẹ́ ẹ bá fi wà pẹ̀lú àwọn ará lóde ẹ̀rí láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ títí kan àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. (1 Pét. 5:1, 2) Àmọ́, kò yẹ kẹ́yin alàgbà jẹ́ kí iṣẹ́ ìjọ tàbí ti àyíká dí yín lọ́wọ́ débi tí ẹ ò fi ní ráyè lọ sóde ẹ̀rí. (Mát. 28:19, 20) Kí ọ̀kan má bàa pa òmíì lára, ó lè gba pé kẹ́ ẹ kọ àwọn iṣẹ́ kan tí wọ́n bá fi lọ̀ yín. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ronú nípa ẹ̀ dáadáa, tẹ́ ẹ sì fi sádùúrà, ẹ lè wá rí i pé tẹ́ ẹ bá gba iṣẹ́ náà, kò ní jẹ́ kẹ́ ẹ ráyè fáwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. Irú bíi ìjọsìn ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, lílọ sóde ẹ̀rí àti dídá àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe ń wàásù. Ẹ fi sọ́kàn pé Jèhófà máa mọyì ẹ̀ gan-an tẹ́ ò bá jẹ́ kí iṣẹ́ kan pa òmíì lára. w22.03 27 ¶4, 7; 28 ¶8
Tuesday, June 27
Ẹ má bẹ̀rù àwọn tó ń pa ara àmọ́ tí wọn ò lè pa ọkàn.—Mát. 10:28.
Ṣé o rántí bí ẹ̀rù ṣe ń ba ìwọ náà nígbà tó o fẹ́ di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Bóyá o tiẹ̀ rò pé o ò ní lè wàásù láti ilé dé ilé, ẹ̀rù sì lè bà ẹ́ pé àwọn ìdílé ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ máa ta kò ẹ́. Tó bá ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá lóye bí nǹkan ṣe rí lára akẹ́kọ̀ọ́ rẹ tí ẹ̀rù bá ń ba òun náà. Jésù náà gbà pé ẹ̀rù lè ba àwọn ọmọlẹ́yìn òun. Àmọ́, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má jẹ́ kí ìbẹ̀rù dí wọn lọ́wọ́ láti sin Jèhófà. (Mát. 10:16, 17, 27) Máa kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ pé kó máa sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn míì. Ó ṣeé ṣe kẹ́rù ba àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù nígbà tó ní kí wọ́n lọ wàásù. Àmọ́ Jésù mú kó rọrùn fún wọn nígbà tó sọ ohun tí wọ́n máa wàásù àti ibi tí wọ́n ti máa wàásù fún wọn. (Mát. 10:5-7) Báwo lo ṣe lè fara wé Jésù? Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ àwọn tó lè wàásù fún. Bí àpẹẹrẹ, o lè bi í pé ṣé ó mọ ẹnì kan tí nǹkan tó ń kọ́ yìí máa ṣe láǹfààní. Kó o wá ràn án lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe máa ṣàlàyé òtítọ́ náà lọ́nà tó rọrùn. w21.06 6 ¶15-16
Wednesday, June 28
Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun iyebíye nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá.—Hág. 2:7.
Lọ́dún 2015, ìmìtìtì ilẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nepal. Àwọn kan tó là á já sọ pé: “Láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan, ọ̀pọ̀ ilé àti ṣọ́ọ̀bù ló wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ.” Ẹlòmíì sọ pé: “Ṣe làyà gbogbo èèyàn ń já . . . Ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé bí ìṣẹ́jú méjì péré ni gbogbo ẹ̀ fi ṣẹlẹ̀, àmọ́ lójú mi ṣe ló dà bí odindi ọjọ́ kan.” Àmọ́ lónìí, ìmìtìtì kan ń ṣẹlẹ̀ tó yàtọ̀ síyẹn, èyí tó jẹ́ pé ó máa kárí ayé ni. Wòlíì Hágáì sọ pé: ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, Lẹ́ẹ̀kan sí i, màá mi ọ̀run àti ayé jìgìjìgì; kò ní pẹ́ mọ́.’ (Hág. 2:6) Ìmìtìtì tí Hágáì sọ tẹ́lẹ̀ máa ń mú káwọn nǹkan rere ṣẹlẹ̀. Ó sì yàtọ̀ pátápátá sí ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń wáyé lónìí tó jẹ́ pé àjálù nìkan ló máa ń fà. Jèhófà fúnra ẹ̀ sọ fún wa pé: “Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun iyebíye nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí.” w21.09 14 ¶1-3
Thursday, June 29
Ẹ̀yin lẹ ti dúró tì mí nígbà àdánwò.—Lúùkù 22:28.
Kí àárín àwọn ọ̀rẹ́ méjì tó lè wọ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ máa bára wọn sọ̀rọ̀ déédéé. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí tó bá kan àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Tá a bá jẹ́ kí Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, èrò wa àtohun tó ń jẹ wá lọ́kàn, ṣe là ń fi hàn pé a fọkàn tán an, a sì gbà pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Sm. 94:17-19; 1 Jòh. 5:14, 15) Máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ará torí àwọn ni ọ̀rẹ́ tòótọ́ tí Jèhófà fi jíǹkí ẹ. (Jém. 1:17) Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó fún wa ní àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ [wa] nígbà gbogbo.” (Òwe 17:17) Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kólósè, ó dárúkọ àwọn ará kan tí wọ́n tì í lẹ́yìn, ó sì pè wọ́n ní “orísun ìtùnú.” (Kól. 4:10, 11) Yàtọ̀ sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, Jésù tún láwọn ọ̀rẹ́ tó jẹ́ áńgẹ́lì, ó sì mọyì bí wọ́n ṣe dúró tì í lásìkò tó nílò wọn. (Lúùkù 22:43) Ti pé a sọ ìṣòro wa fún ẹnì kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ kò túmọ̀ sí pé a ò lè dá ìpinnu ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́. w21.04 24-25 ¶14-16
Friday, June 30
[Ìfẹ́] máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra, ó máa ń gba ohun gbogbo gbọ́, ó máa ń retí ohun gbogbo, ó máa ń fara da ohun gbogbo.—1 Kọ́r. 13:7.
Kí ló yẹ kó o ṣe tí ẹnì kan nínú ìjọ bá ṣe ohun tó dùn ẹ́? Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà. Á dáa kó o sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà. Bẹ Jèhófà pé kó bù kún ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́, kó o sì sọ pé kó jẹ́ kó o máa rí ibi tí ẹni náà dáa sí, ìyẹn àwọn ohun tí Jèhófà rí tó fi nífẹ̀ẹ́ ẹni náà. (Lúùkù 6:28) Tó bá jẹ́ pé o ò lè gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, wá bó o ṣe lè fọgbọ́n bá ẹni náà sọ ọ́. Ohun tó dáa jù ni pé ká gbà nínú ọkàn wa pé ẹni náà ò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó dùn wá. (Mát. 5:23, 24) Tá a bá ti lọ bá a sọ̀rọ̀, ká gba ohun tó sọ gbọ́. Tí ẹni náà ò bá gbà pẹ̀lú wa ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa fara dà á fún ara yín.” Torí náà, gbà pé ó ṣì lè ṣàtúnṣe. (Kól. 3:13) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, má ṣe di ẹni náà sínú torí ìyẹn lè kó bá àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà. Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun tí ẹnikẹ́ni bá ṣe mú ẹ kọsẹ̀ láé. Tó o bá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn á fi hàn pé o ka àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà sí pàtàkì ju ohunkóhun míì lọ.—Sm. 119:165. w21.06 23 ¶15