July
Saturday, July 1
Tó bá yá, [ìbáwí] máa ń so èso àlàáfíà ti òdodo fún àwọn tí a ti fi dá lẹ́kọ̀ọ́.—Héb. 12:11.
Jèhófà ló ṣètò pé kí wọ́n máa yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. Ètò yìí máa ṣe gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ láǹfààní títí kan oníwà àìtọ́ náà. Àwọn kan nínú ìjọ lè sọ pé kò yẹ kí wọ́n yọ ẹni náà lẹ́gbẹ́. Àmọ́ rántí pé, àwọn tó máa ń ṣàríwísí yìí kì í sábà mẹ́nu kan àwọn nǹkan tí ò dáa tí oníwà àìtọ́ náà ṣe. Òótọ́ kan ni pé, a ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Torí náà, ohun tó máa bọ́gbọ́n mu ni pé kó o fara mọ́ ìpinnu táwọn alàgbà náà ṣe, kó o sì gbà pé wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. Ká tún fi sọ́kàn pé kì í ṣe èèyàn ni wọ́n ń ṣojú fún bí wọ́n ṣe ń dájọ́, “Jèhófà ni.” (2 Kíró. 19:6) Tó o bá fara mọ́ ìpinnu táwọn alàgbà ṣe láti yọ ẹnì kan nínú ìdílé ẹ lẹ́gbẹ́, ìyẹn lè mú kẹ́ni náà pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Elizabeth sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti má ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ọmọ mi. Àmọ́ lẹ́yìn tó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, òun fúnra ẹ̀ gbà pé ó dáa bí wọ́n ṣe yọ òun lẹ́gbẹ́. Nígbà tó yá, ó sọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan lòun kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ náà.” w21.09 28-29 ¶11-12
Sunday, July 2
Ó rí opó aláìní kan tó fi ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré gan-an síbẹ̀.—Lúùkù 21:2.
Kò sí àní-àní pé ó máa wu opó náà pé kó ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fún Jèhófà. Síbẹ̀, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, ó fún Jèhófà ní gbogbo ohun tó ní. Jésù sì mọ̀ pé Jèhófà mọyì ohun tó ṣe yẹn gan-an. Ẹ̀kọ́ pàtàkì ibẹ̀ ni pé inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá fi tọkàntọkàn ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. (Mát. 22:37; Kól. 3:23) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Jèhófà bó ṣe ń rí bá a ṣe ń sapá láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀! Tá a bá fi ẹ̀kọ́ yìí sọ́kàn, àá fi kún àkókò àti okun tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àá sì máa fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìpàdé wa. Báwo lo ṣe lè fi ohun tó o kọ́ lára opó náà sílò? Ronú nípa àwọn tí ipò wọn ò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kó o sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà mọyì ohun tí wọ́n ń ṣe báyìí. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa dun arábìnrin àgbàlagbà kan pé òun ò lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. w21.04 6 ¶17, 19-20
Monday, July 3
Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fara da àdánwò, torí tó bá rí ìtẹ́wọ́gbà, ó máa gba adé ìyè.—Jém. 1:12.
Jèhófà mọ ìgbà tó dáa jù láti fòpin sí ayé burúkú yìí. Sùúrù tó ní ló mú kí ogunlọ́gọ̀ èèyàn láǹfààní láti máa jọ́sìn rẹ̀ kí wọ́n sì máa yìn ín. Inú wọn ń dùn pé Jèhófà mú sùúrù títí di àkókò yìí. Ká sọ pé Jèhófà ti pa ayé búburú yìí run ni, wọn ò bá má bí wọn rárá, débi tí wọ́n á kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí wọ́n á sì ya ara wọn sí mímọ́ fún un. Nígbà tí Jèhófà bá pa ayé burúkú yìí run, ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó fara dà á dé òpin máa gba èrè wọn. Inú wọn máa dùn, wọ́n á sì gbà pé ó tọ́ bí Jèhófà ṣe mú sùúrù fún gbogbo wọn! Láìka gbogbo ìṣòro tí Sátánì ń fà, Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà. (1 Tím. 1:11) Ó yẹ káwa náà máa láyọ̀ bá a ṣe ń fi sùúrù dúró dìgbà tí Jèhófà máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, táá fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run, táá fòpin sí ìwà burúkú, táá sì mú gbogbo ìṣòro wa kúrò. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa fara dà á torí a mọ̀ pé Baba wa ọ̀run náà ń fara dà á. w21.07 13 ¶18-19
Tuesday, July 4
Ṣé ohun rere kankan lè wá láti Násárẹ́tì?—Jòh. 1:46.
Ọ̀pọ̀ ò gba Jésù gbọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Lójú wọn, ọmọ káfíńtà lásánlàsàn ni. Yàtọ̀ síyẹn Násárẹ́tì ló ti wá, àwọn èèyàn ò sì ka ìlú yìí sí pàtàkì rárá. Kódà, Nàtáníẹ́lì tó pa dà wá di ọmọlẹ́yìn Jésù sọ nígbà kan pé: “Ṣé ohun rere kankan lè wá láti Násárẹ́tì?” Ó lè jẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Míkà 5:2 ló wà lọ́kàn ẹ̀ tó sọ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n máa bí Mèsáyà náà sí, kì í ṣe Násárẹ́tì. Wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọ̀tá Jésù kò ní fiyè sí ‘kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìran tí Mèsáyà’ ti wá. (Àìsá. 53:8) Ká sọ pé àwọn èèyàn yẹn fara balẹ̀ gbé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yẹn yẹ̀ wò ni, wọ́n á rí i pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n bí Jésù sí àti pé àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì ni. (Lúùkù 2:4-7) Torí náà, ibi tí wọ́n bí Jésù sí bá àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Míkà 5:2 mu. Kí wá nìṣòro àwọn èèyàn náà? Ìṣòro wọn ni pé wọn ò ṣe ìwádìí dáadáa, wọn ò sì rídìí ọ̀rọ̀. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ wọn fi kọsẹ̀. w21.05 2-3 ¶4-6
Wednesday, July 5
Tí olódodo bá . . . bá mi wí, á dà bí òróró ní orí mi.Sm. 141:5.
Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó gba ìbùkún nítorí pé wọ́n gba ìbáwí. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jóòbù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni, síbẹ̀ ó bẹ̀rù Ọlọ́run. Nígbà tí ìdààmú bá a, ó sọ nǹkan tí kò yẹ kó sọ. Ìyẹn ló jẹ́ kí Jèhófà àti Élíhù bá a wí. Ṣé Jóòbù gba ìbáwí náà? Bẹ́ẹ̀ ni. Ó sọ pé: ‘Mo sọ̀rọ̀, àmọ́ mi ò lóye, mo kó ọ̀rọ̀ mi jẹ, mo sì ronú pìwà dà nínú iyẹ̀pẹ̀ àti eérú.’ (Jóòbù 42:3-6, 12-17) Ó fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ nígbà tó gba ìbáwí tí Élíhù fún un, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Élíhù kéré sí i lọ́jọ́ orí. (Jóòbù 32:6, 7) Ìrẹ̀lẹ̀ tún máa jẹ́ ká ṣiṣẹ́ lórí ìbáwí tí wọ́n fún wa kódà tó bá ń ṣe wá bíi pé kò yẹ kí wọ́n fún wa nírú ìbáwí yẹn tàbí tí ẹni tó sọ fún wa bá kéré sí wa lọ́jọ́ orí. Gbogbo wa ló yẹ ká ṣiṣẹ́ kára ká lè túbọ̀ ní èso tẹ̀mí, ká sì túbọ̀ já fáfá nínú iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. w22.02 11 ¶8; 12 ¶12
Thursday, July 6
Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.—Jòh. 13:35.
Ojúṣe gbogbo wa ni láti rí i pé ìfẹ́ àti àlàáfíà jọba nínú ìjọ, kó má sì ṣe ẹnikẹ́ni bíi pé òun ò rẹ́ni fojú jọ. Èyí fi hàn pé ohun tá a bá ṣe àtohun tá a bá sọ lè fún àwọn míì níṣìírí gan-an. Ìbéèrè náà ni pé kí la lè ṣe táá mú kára tu àwọn tí kò ní ẹbí nínú òtítọ́? Mú àwọn ẹni tuntun lọ́rẹ̀ẹ́. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá kí àwọn ẹni tuntun dáadáa tí wọ́n bá wá sípàdé wa. (Róòmù 15:7) Àmọ́, kò yẹ ká fi mọ síbẹ̀ o. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó tún yẹ ká mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Torí náà, sún mọ́ àwọn ẹni tuntun kó o lè túbọ̀ mọ̀ wọ́n. A tún lè sapá láti mọ ohun tí wọ́n ń kojú láìtojú bọ ọ̀rọ̀ wọn. Ó lè má rọrùn fáwọn kan láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn. Torí náà, kò ní dáa kó o lọ́ wọn nífun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o fọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè táá jẹ́ kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, kó o sì tẹ́tí sí wọn dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, o lè bi wọ́n pé, báwo lẹ ṣe rí òtítọ́? w21.06 11 ¶13-14
Friday, July 7
Wọ́n á fetí sí ohùn mi, wọ́n á sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.—Jòh. 10:16.
Gbogbo wa pátá la mọyì àǹfààní tá a ní láti máa sin Jèhófà níṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan”! Ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 165 sọ pé: “Bí ìwọ náà ṣe ń jàǹfààní ìṣọ̀kan yìí, ó yẹ kó o jẹ́ kó máa gbèrú sí i.” Torí náà, ó yẹ ká ‘jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa ka àwọn ará wa sẹ́ni ọ̀wọ́n.’ Ká má gbàgbé pé gbogbo wa la ṣeyebíye lójú Jèhófà, bá a tiẹ̀ jẹ́ “ẹni kékeré.” Ṣé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa náà ṣeyebíye lójú wa? Ẹ jẹ́ ká máa fi sọ́kàn pé gbogbo bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wọn, tá a sì ń bójú tó wọn ni Jèhófà ń kíyè sí. (Mát. 10:42) A nífẹ̀ẹ́ àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Torí náà, a ti ‘pinnu pé a ò ní fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí ohun ìdènà síwájú àwọn arákùnrin wa.’ (Róòmù 14:13) A gbà pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa sàn jù wá lọ. Torí náà, a fẹ́ máa dárí jì wọ́n látọkàn wá. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ká má ṣe jẹ́ kí ìwà àwọn míì mú wa kọsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà àti àwọn ohun tó ń gbé ẹnì kejì wa ró.”—Róòmù 14:19. w21.06 24 ¶16-17
Saturday, July 8
Ọlọ́run . . . ń mú kó dàgbà.—1 Kọ́r. 3:7.
Tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, tá a sì ń fi àwọn ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sílò, díẹ̀díẹ̀ a máa dà bíi Kristi. Yàtọ̀ síyẹn, àá túbọ̀ máa mọ Jèhófà sí i. Jésù lo àpèjúwe bí irúgbìn ṣe ń dàgbà láti jẹ́ ká mọ bí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń mú káwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yí pa dà díẹ̀díẹ̀. Ó sọ pé: “Irúgbìn náà rú jáde, ó sì dàgbà, àmọ́ [afúnrúgbìn náà] kò mọ bó ṣe ṣẹlẹ̀. Ilẹ̀ náà mú èso jáde fúnra rẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ohun ọ̀gbìn náà kọ́kọ́ yọ, lẹ́yìn náà erín ọkà, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èso jáde lódindi nínú erín ọkà.” (Máàkù 4:27, 28) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé bó ṣe jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni irúgbìn kan máa ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni ẹni tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ máa ń tẹ̀ síwájú. Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá máa rí àwọn ìyípadà tí wọ́n ń ṣe nígbèésí ayé wọn. (Éfé. 4:22-24) Àmọ́ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà ló ń mú kí irúgbìn kékeré yẹn dàgbà.—w21.08 8-9 ¶4-5
Sunday, July 9
Ó sàn kéèyàn máa gbádùn ohun tí ojú rẹ̀ rí ju kó máa dààmú lórí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́.—Oníw. 6:9.
A lè láyọ̀ tá a bá wá a lọ́nà tó tọ́. Ẹni tó ń gbádùn “ohun tí ojú rẹ̀ rí” mọyì ohun tó ní báyìí. Àmọ́ ẹni tó ń dààmú lórí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ kò ní ní ìtẹ́lọ́rùn, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó láyọ̀. Kí nìyẹn kọ́ wa? Tá a bá fẹ́ láyọ̀, á dáa ká pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tá a ní báyìí dípò ká máa da ara wa láàmú lórí ohun tí ọwọ́ wa ò lè tẹ̀. Àmọ́, ṣé ó ṣeé ṣe kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tó ní báyìí? Àwọn kan gbà pé kò ṣeé ṣe, ó ṣe tán bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ó máa ń wù wá pé ká ní àwọn nǹkan míì. Bó ti wù kó rí, ó ṣeé ṣe kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn. A lè gbádùn ohun tí ‘ojú wa rí,’ kì í kàn ṣe ká gba kámú pẹ̀lú ẹ̀. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ká lè rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe tálẹ́ńtì tí Jésù ṣe nínú Mátíù 25:14-30 ká sì rí ohun tá a lè ṣe táá jẹ́ kí àwọn àǹfààní tá a ní báyìí máa fún wa láyọ̀ àti ohun táá jẹ́ kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i. w21.08 21 ¶5-6
Monday, July 10
Ibi gíga àti ibi mímọ́ ni mò ń gbé, àmọ́ mo tún ń gbé pẹ̀lú àwọn tí a tẹ̀ rẹ́, tí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí.—Àìsá. 57:15.
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tí a “tẹ̀ rẹ́, tí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí,” ó sì ń bójú tó wọn. Kì í ṣe àwọn alàgbà nìkan ló lè fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí níṣìírí, gbogbo wa ló yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká fìfẹ́ hàn sí wọn. Ìfẹ́ tá a bá fi hàn sí wọn á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn gan-an. (Òwe 19:17) Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká má sì máa fọ́nnu. Kò yẹ ká máa pe àfiyèsí sí ara wa ṣáá torí ìyẹn lè jẹ́ káwọn míì bẹ̀rẹ̀ sí í jowú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó máa gbé àwọn ará ró ló yẹ ká máa sọ ká sì máa ṣe. (1 Pét. 4:10, 11) A lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn míì tá a bá wo ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Nínú gbogbo àwọn tó tíì gbé ayé yìí, kò sẹ́ni tó dà bíi Jésù. Síbẹ̀, “oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn” ni. (Mát. 11:28-30) Ọ̀rọ̀ tó máa yé tèwe tàgbà ló máa ń lò, ó sì lo àwọn àpèjúwe tó ń wọni lọ́kàn.—Lúùkù 10:21. w21.07 23 ¶11-12
Tuesday, July 11
Bi àwọn àgbààgbà rẹ, wọ́n á sì jẹ́ kí o mọ̀.—Diu. 32:7.
Wáyè láti bá àwọn àgbàlagbà sọ̀rọ̀. Lóòótọ́, ojú wọn lè ti di bàìbàì, ara wọn lè má ta pọ́ún pọ́ún bíi ti tẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ sì lè má já geere lẹ́nu wọn mọ́. Síbẹ̀, ó máa ń wù wọ́n láti ṣe púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn, wọ́n sì ti ṣe “orúkọ rere” fún ara wọn lọ́dọ̀ Jèhófà. (Oníw. 7:1) Máa rántí pé Jèhófà mọyì wọn. Torí náà, ó yẹ kíwọ náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Á dáa kó o ṣe bí Èlíṣà. Lọ́jọ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú Èlíjà, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sọ fún Èlíjà pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” (2 Ọba 2:2, 4, 6) O lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn àgbàlagbà dénú tó o bá ń béèrè àwọn ìbéèrè táá jẹ́ kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. (Òwe 1:5; 20:5; 1 Tím. 5:1, 2) O lè bi wọ́n pé: “Nígbà tẹ́ ẹ wà lọ́dọ̀ọ́, kí ló mú kó dá yín lójú pé ẹ ti rí òtítọ́?” “Báwo làwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí yín ṣe mú kẹ́ ẹ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?” “Kí ló ń fún yín láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?” (1 Tím. 6:6-8) Lẹ́yìn náà, fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn. w21.09 5 ¶14; 7 ¶15
Wednesday, July 12
Ọlọ́run ni ẹni tó ń fún yín lágbára nítorí ìdùnnú rẹ̀, ó ń mú kó wù yín láti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń fún yín ní agbára láti ṣe é.—Fílí. 2:13.
Tó o bá ń sapá láti pa àṣẹ Jésù mọ́ tó ní ká wàásù ká sì sọni dọmọ ẹ̀yìn, ṣe lò ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. (1 Jòh. 5:3) Wò ó báyìí ná: Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ló mú kó o máa wàásù láti ilé dé ilé, àmọ́ ṣó rọrùn? Kò dájú. Ṣé ẹ̀rù bà ẹ́ nígbà tó o kọ́kọ́ wàásù láti ilé dé ilé? Kò sí àní-àní pé ẹ̀rù bà ẹ́. Àmọ́ torí pé o mọ̀ pé iṣẹ́ tí Jésù fẹ́ kó o ṣe nìyẹn, o ṣe bẹ́ẹ̀, o ò sì jẹ́ kó sú ẹ. Bọ́jọ́ sì ṣe ń gorí ọjọ́, ó túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti máa wàásù. Àmọ́ tó bá di pé kó o máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ńkọ́? Ṣé ìyẹn náà máa ń bà ẹ́ lẹ́rù? Ó ṣeé ṣe. Àmọ́, tó o bá bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o borí ìbẹ̀rù ẹ kó o sì ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Jèhófà máa mú kó wù ẹ́ láti máa sọni dọmọ ẹ̀yìn. w21.07 3 ¶7
Thursday, July 13
Kí wọ́n sàmì sí ọwọ́ ọ̀tún wọn tàbí iwájú orí wọn.—Ìfi. 13:16.
Láyé àtijọ́, wọ́n máa ń sàmì sára àwọn ẹrú kí wọ́n lè mọ olówó wọn. Bákan náà lónìí, wọ́n máa fẹ́ kí gbogbo èèyàn gba àmì sí ọwọ́ wọn tàbí síwájú orí wọn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ó máa hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe àwọn tó bá gba àmì náà pé ìjọba ayé ni wọ́n ń tì lẹ́yìn. Ṣé a máa gba àmì ìṣàpẹẹrẹ yìí ká sì tipa bẹ́ẹ̀ ti àwọn ìjọba ayé yìí lẹ́yìn? Wọ́n máa ṣenúnibíni sí àwọn tí kò bá gba àmì náà, wọ́n sì máa fìyà jẹ wọ́n gan-an. Ìwé Ìfihàn sọ pé: “Ẹnì kankan [ò ní] lè rà tàbí tà àfi ẹni tó bá ní àmì náà.” (Ìfi. 13:17) Àmọ́ ẹ̀rù ò ba àwa èèyàn Ọlọ́run torí a mọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fáwọn tó bá gba àmì náà bó ṣe wà nínú Ìfihàn 14:9, 10. Dípò kí wọ́n gba àmì náà, ohun tí wọ́n máa kọ sí ọwọ́ wọn ni “Ti Jèhófà.” (Àìsá. 44:5) Ìsinsìnyí gan-an la gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà á dùn láti kà wá mọ́ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀! w21.09 18 ¶15-16
Friday, July 14
Bí irin ṣe ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ṣe ń pọ́n ọ̀rẹ́ rẹ̀.—Òwe 27:17.
Tá a bá fẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù wa sèso rere, ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn míì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí Tímótì mọ bí òun ṣe ń wàásù àti bí òun ṣe ń kọ́ni, ó sì gba Tímótì níyànjú pé kóun náà máa wàásù kó sì máa kọ́ni lọ́nà yẹn. (1 Kọ́r. 4:17) Bíi ti Tímótì, àwa náà lè kẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ àwọn tó nírìírí nínú ìjọ wa. Yàtọ̀ síyẹn, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ ẹ sọ́nà ní gbogbo ìgbà tó o bá lọ sóde ẹ̀rí. Kò sí ohun tá a lè dá ṣe láìsí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́. (Sm. 127:1; Lúùkù 11:13) Tó o bá ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́, sọ ohun tó o fẹ́ kó ṣe fún ẹ ní pàtó. Bí àpẹẹrẹ, bẹ̀ ẹ́ pé kó darí ẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ tí wọ́n sì ṣe tán láti gbọ́. Kó o wá fi iṣẹ́ ti àdúrà náà lẹ́yìn, kó o sì wàásù fún gbogbo àwọn tó o bá pàdé. Ó yẹ ká tún máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: ‘Fúnra rẹ ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.’ (Róòmù 12:2) Bí òtítọ́ tá a mọ̀ nípa Ọlọ́run bá ṣe dá wa lójú tó, bẹ́ẹ̀ làá máa fìgboyà wàásù fáwọn èèyàn. w21.05 18 ¶14-16
Saturday, July 15
Làálàá yín kò ní já sí asán nínú Olúwa.—1 Kọ́r. 15:58.
Ká sọ pé o ti sa gbogbo ipá ẹ, o sì ti gbàdúrà nítorí ẹnì kan tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ tí ò tẹ̀ síwájú, tó o wá rí i pé ó yẹ kó o dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Tó bá jẹ́ pé o ò tíì kọ́ ẹnì kankan lẹ́kọ̀ọ́ débi tó fi ṣèrìbọmi ńkọ́? Ṣé ó yẹ kó o wá máa rò pé Jèhófà ò tíì bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? Iṣẹ́ àṣekára àti ìfaradà wa ni Jèhófà máa ń wò. Bá a ṣe ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló fi ń díwọ̀n àṣeyọrí wa, kì í ṣe bóyá àwọn èèyàn gbọ́ wa tàbí wọn ò gbọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀ bí ẹ ṣe ń ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, tí ẹ sì ń bá a lọ láti ṣe ìránṣẹ́.” (Héb. 6:10) Jèhófà ò gbàgbé iṣẹ́ àṣekára wa àti ìfẹ́ tá a ní fún un kódà bí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ò bá tiẹ̀ ṣèrìbọmi. Torí náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní máa fún ẹ ní ìṣírí. w21.10 25 ¶4-6
Sunday, July 16
Gbogbo àwọn tí Baba fún mi máa wá sọ́dọ̀ mi, mi ò sì ní lé ẹni tó bá wá sọ́dọ̀ mi kúrò láé.—Jòh. 6:37.
Ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì ń gba tiwọn rò. Jésù mọ̀ pé ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ní àti pé ohun tágbára wọn gbé yàtọ̀ síra. Torí náà, ohun tí kálukú wọn lè bójú tó yàtọ̀ síra, ohun tí wọ́n sì lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ò dọ́gba. Síbẹ̀ Jésù mọyì iṣẹ́ takuntakun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣe. Èyí sì ṣe kedere nínú àkàwé nípa tálẹ́ńtì tó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Nínú àkàwé yẹn, ọ̀gá kan fún àwọn ẹrú rẹ̀ níṣẹ́ “bí agbára [ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn] ṣe mọ.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èrè tí ọ̀kan lára àwọn ẹrú náà rí ju ti èkejì lọ, ọ̀rọ̀ kan náà ni ọ̀gá wọn fi gbóríyìn fún wọn. Ó ní: “O káre láé, ẹrú rere àti olóòótọ́!” (Mát. 25:14-23) Jésù nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa ń gba tiwa rò. Ó mọ̀ pé ohun tá a lè ṣe ò dọ́gba, ipò wa sì yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, inú ẹ̀ máa ń dùn tá a bá ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé. Torí náà, ó yẹ káwa náà máa fìfẹ́ hàn sáwọn míì, ká sì máa gba tiwọn rò bíi ti Jésù. w21.07 23 ¶12-14
Monday, July 17
Mi ò ní gbé ọwọ́ mi sókè sí olúwa mi.—1 Sám. 24:10.
Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Ọba Dáfídì máa ń fàánú hàn. Bí àpẹẹrẹ, èèyàn líle ni Nábálì. Nígbà tí Dáfídì rán àwọn ọkùnrin kan pé kí wọ́n lọ béèrè oúnjẹ lọ́wọ́ Nábálì, ṣe ni Nábálì sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn. Inú bí Dáfídì gan-an, ó sì pinnu pé òun máa pa Nábálì àti gbogbo ọkùnrin tó wà nílé rẹ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ Ábígẹ́lì ìyàwó Nábálì tó tètè gbé ìgbésẹ̀ láti pèsè oúnjẹ fún Dáfídì àtàwọn ọkùnrin ẹ̀. Ìyẹn sì ni ò jẹ́ kí Dáfídì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. (1 Sám. 25:9-22, 32-35) Ẹ kíyè sí i pé ìbínú mú kí Dáfídì dájọ́ ikú fún Nábálì àtàwọn ọkùnrin tó wà nílé rẹ̀. Bákan náà, Dáfídì dájọ́ ikú fún ọkùnrin tó wà nínú àpèjúwe Nátánì. Nínú àpẹẹrẹ kejì, a lè máa ṣe kàyéfì pé ṣebí ọlọ́kàn tútù ni Dáfídì, kí wá nìdí tó fi dájọ́ olè náà lọ́nà tó le tóyẹn. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn. Torí pé Dáfídì ti dẹ́ṣẹ̀, ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ń dá a lẹ́bi. Torí náà, tẹ́nì kan bá ti le jù tàbí tó ń dá àwọn míì lẹ́jọ́, ìyẹn fi hàn pé ẹni náà ò ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. w21.10 12 ¶17-18; 13 ¶20
Tuesday, July 18
Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, torí èmi jẹ́ mímọ́.—1 Pét. 1:16.
Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní jẹ́ ká mọ̀ pé a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà ẹni tó fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ìjẹ́mímọ́. Torí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ nínú ìwà wa. Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé kò ṣeé ṣe torí aláìpé ni wá. Àmọ́, àpọ́sítélì Pétérù náà ṣe àwọn àṣìṣe kan, síbẹ̀ àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ fi hàn pé a lè jẹ́ mímọ́. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó jẹ́ mímọ́, ohun táwọn èèyàn máa ń rò ni ẹnì kan tí inú ẹ̀ kì í dùn, tó wọ aṣọ ẹ̀sìn, tí ìrísí ẹ̀ sì jọ ẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run. Àmọ́, èrò yìí ò tọ̀nà torí pé Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, “Ọlọ́run aláyọ̀” sì ni. (1 Tím. 1:11) Bíbélì tún pe àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà ní “aláyọ̀.” (Sm. 144:15) Kódà, Jésù ò fara mọ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó ń wọ aṣọ ńlá, tí wọ́n sì ń ṣe òdodo wọn níwájú àwọn èèyàn. (Mát. 6:1; Máàkù 12:38) Àmọ́ ní ti àwa Kristẹni tòótọ́, ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì ló jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ káwa náà jẹ́ mímọ́. A sì mọ̀ dájú pé Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ ò ní fún wa lófin tá ò ní lè pa mọ́. w21.12 2 ¶1, 3
Wednesday, July 19
Kí o sì fi gbogbo ọkàn rẹ . . . nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.—Máàkù 12:30.
Nínú gbogbo nǹkan rere tí Jèhófà fún wa, ọ̀kan lára èyí tó ga jù ni àǹfààní tá a ní láti máa sìn ín. A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tá a bá ń “pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (1 Jòh. 5:3) Ọ̀kan lára àwọn àṣẹ Jèhófà tó yẹ ká pa mọ́ lèyí tí Jésù sọ pé ká sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn, ká sì máa batisí wọn. (Mát. 28:19) Ó tún pàṣẹ pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa. (Jòh. 13:35) Jèhófà máa mú káwọn tó bá ṣègbọràn di ara ìdílé ẹ̀ kárí ayé. (Sm. 15:1, 2) Fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn míì. Ìfẹ́ ló gbawájú nínú àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní. (1 Jòh. 4:8) Ká tó mọ Jèhófà rárá ló ti ń fìfẹ́ hàn sí wa. (1 Jòh. 4:9, 10) Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn míì, ṣe là ń fi hàn pé a fìwà jọ Jèhófà. (Éfé. 5:1) Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ni pé ká kọ́ wọn nípa Jèhófà nígbà tí àkókò ṣì wà. (Mát. 9:36-38) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fún wọn láǹfààní láti di ara ìdílé Ọlọ́run. w21.08 5-6 ¶13-14
Thursday, July 20
Kò sí ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ ju èyí lọ.—Jòh. 15:13.
Nítorí pé Jésù nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Bàbá rẹ̀ gan-an, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. (Jòh. 14:31) Ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀ nígbà tó wà láyé fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an. Ojoojúmọ́ ni Jésù ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó sì máa ń ṣàánú wọn, kódà ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà táwọn kan ta kò ó. Ọ̀nà pàtàkì kan tí Jésù gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ni pé ó máa ń kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 4:43, 44) Jésù tún fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn, torí ó gbà káwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pa òun, ó sì kú ikú oró. Ohun tí Jésù ṣe yìí ló jẹ́ ká nírètí pé a máa wà láàyè títí láé. Ìdí tá a fi ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì ṣèrìbọmi ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Torí náà, bíi ti Jésù, tá a bá ń ṣe ohun tó dáa sáwọn èèyàn, àwa náà ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nìyẹn. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ tó rí, kò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí kò rí.”—1 Jòh. 4:20. w22.03 10 ¶8-9
Friday, July 21
Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe bí aláìlọ́gbọ́n àmọ́ bí ọlọ́gbọ́n, kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.—Éfé. 5:15, 16.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń gbádùn àwọn àkókò tá a máa ń lò láti gbàdúrà sí Jèhófà, tá a sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Síbẹ̀, àwọn nǹkan kan ṣì wà tó máa ń gba àkókò wa. Ọwọ́ wa máa ń dí gan-an, ìyẹn ni kì í jẹ́ kó rọrùn fún wa láti ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, bá a ṣe máa bójú tó ìdílé wa àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì lè gba àkókò wa débi pé a lè má ráyè gbàdúrà, ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì ṣàṣàrò lórí ohun tá a kọ́. Àwọn nǹkan míì wà tá ò fura sí tó lè gba àkókò wa. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè gba àwọn nǹkan tí ò burú láyè láti gba àkókò tó yẹ ká fi jọ́sìn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, àkókò tá a fi ń ṣeré tàbí najú. Gbogbo wa la máa ń gbádùn àkókò tá a fi ń sinmi. Àmọ́ àwọn eré tó dáa lè gba àkókò wa débi pé àkókò tó máa ṣẹ́ kù fún ìjọsìn Ọlọ́run ò ní tó nǹkan. Torí náà, ó yẹ ká mọ̀ pé kò yẹ ká jẹ́ kí àkókò eré dí ìjọsìn Ọlọ́run lọ́wọ́.—Òwe 25:27; 1 Tím. 4:8. w22.01 26 ¶2-3
Saturday, July 22
Kí ẹ máa ṣe àjèjì tó ń bá yín gbé bí ọmọ ìbílẹ̀; kí ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ara yín.—Léf. 19:34.
Nígbà tí Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn, kì í ṣe ẹ̀yà wọn tàbí orílẹ̀-èdè wọn nìkan ló ní lọ́kàn. Ó tún sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì tó wà láàárín wọn. Ohun tó wà nínú Léfítíkù 19:33, 34 sì yé wọn dáadáa. Wọ́n gbọ́dọ̀ máa hùwà sí àjèjì bí “ọmọ ìbílẹ̀,” wọ́n sì gbọ́dọ̀ “nífẹ̀ẹ́ rẹ̀” bí ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti gba àjèjì àtàwọn aláìní láàyè láti máa pèéṣẹ́ nínú oko wọn. (Léf. 19:9, 10) Ìlànà tó sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì kan àwa Kristẹni náà lóde òní. (Lúùkù 10:30-37) Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Àìmọye àwọn àjèjì ló wà kárí ayé lónìí, àwọn kan sì lè máa gbé nítòsí wa. Ó yẹ ká máa hùwà tó dáa sí wọn, lọ́kùnrin, lóbìnrin àti lọ́mọdé, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. w21.12 12 ¶16
Sunday, July 23
Àwọn tó ń wá Jèhófà, . . . kò ní ṣaláìní ohun rere.—Sm. 34:10.
Tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára báyìí láti máa gbára lé Jèhófà, ọkàn wa á túbọ̀ balẹ̀ pé á ràn wá lọ́wọ́, á sì dáàbò bò wá lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, ó gba ìgbàgbọ́, ó sì gba pé kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kéèyàn tó lè lọ tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀gá ẹ̀ pé òun fẹ́ lọ sí àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ agbègbè. Ohun kan náà ló máa gbà kéèyàn tó lè béèrè pé kí wọ́n fún òun láyè láti máa lọ sí gbogbo ìpàdé, kóun sì tún máa jáde òde ẹ̀rí déédéé. Àmọ́ ká wá sọ pé ọ̀gá wa ò fún wa láyè, tí iṣẹ́ sì bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́ ńkọ́? Ṣé a nígbàgbọ́ pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ tàbí pa wá tì láé àti pé ó máa pèsè àwọn ohun tá a nílò? (Héb. 13:5) Àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ti rí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Wọ́n láwọn ìrírí tó fi hàn pé Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n wà nínú ìṣòro. Ká sòótọ́, adúrótini ni Jèhófà. Torí pé Jèhófà wà lẹ́yìn wa, kò sídìí pé à ń bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó dá wa lójú pé Baba wa ọ̀run ò ní fi wá sílẹ̀ láé. Ìyẹn tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Ìjọba rẹ̀ ló gbawájú láyé wa. w22.01 7 ¶16-17
Monday, July 24
Kì í ṣe èèyàn lẹ̀ ń ṣojú fún tí ẹ bá ń dájọ́, Jèhófà ni.—2 Kíró. 19:6.
Kí ló lè dán wa wò bóyá a fọkàn tán àwọn alàgbà? Ká sọ pé ẹni tó sún mọ́ wa gan-an ni wọ́n yọ kúrò nínú ìjọ. A lè máa rò ó pé wọn ò gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa tàbí ká máa rò pé wọn ò dá ẹjọ́ náà bí Jèhófà ṣe fẹ́. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara mọ́ ohun táwọn alàgbà bá ṣe? Ó yẹ ká rántí pé Jèhófà ló ṣètò pé kí wọ́n yọ ẹni tó bá hùwà àìtọ́ kúrò nínú ìjọ, èyí sì máa ṣe ìjọ àti oníwà àìtọ́ náà láǹfààní. Tí wọ́n bá gba oníwà àìtọ́ láyè láti wà nínú ìjọ, ó lè mú káwọn ẹlòmíì máa dẹ́ṣẹ̀. (Gál. 5:9) Yàtọ̀ síyẹn, ó lè má mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ tóun dá ṣe burú tó, ó tiẹ̀ lè má ronú láti ṣàtúnṣe kó lè pa dà rí ojúure Jèhófà. (Oníw. 8:11) Ohun kan tó dájú ni pé táwọn alàgbà bá fẹ́ pinnu bóyá kí wọ́n yọ ẹnì kan kúrò nínú ìjọ, wọ́n máa ń ronú dáadáa kí wọ́n tó ṣe bẹ́ẹ̀. w22.02 5-6 ¶13-14
Tuesday, July 25
Kò ní fọ́ esùsú kankan tó ti ṣẹ́, kò sì ní pa òwú àtùpà kankan tó ń jó lọ́úlọ́ú, tí wọ́n fi ọ̀gbọ̀ ṣe.—Mát. 12:20.
Ó yẹ kẹ́yin alàgbà máa fi inúure hàn kẹ́ ẹ sì máa ní sùúrù, pàápàá tí ẹni tẹ́ ẹ fún nímọ̀ràn ò bá gba ìmọ̀ràn náà. Alàgbà kan ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí inú bí òun tí ẹni tó fún nímọ̀ràn ò bá gba ìmọ̀ràn náà tàbí tí kò tètè ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀. Torí náà, tí alàgbà náà bá ń dá gbàdúrà, ó lè bẹ Jèhófà pé kó ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè rí ìdí tí wọ́n fi ń gba òun nímọ̀ràn àti ìdí tó fi yẹ kóun ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀. Ó lè gba pé kó fún ẹni náà ní àkókò díẹ̀ kó lè ronú lórí ohun tó bá a sọ. Tí alàgbà náà bá ní sùúrù tó sì fi inúure hàn, ẹni tó gbà nímọ̀ràn náà ò ní wo ọ̀nà tó gbà bá òun sọ̀rọ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn tó fún un ló máa gbájú mọ́. Síbẹ̀, ó yẹ kí alàgbà náà fi sọ́kàn pé Ìwé Mímọ́ ló yẹ kóun máa fi gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn nígbà gbogbo. A fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, àmọ́ a tún fẹ́ “mú ọkàn [wọn] yọ̀.”—Òwe 27:9. w22.02 18 ¶17; 19 ¶19
Wednesday, July 26
Ìrètí pípẹ́ máa ń mú ọkàn ṣàìsàn.—Òwe 13:12.
Tá a bá gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa lókun láti fara da ìṣòro kan tàbí kùdìẹ̀-kudiẹ kan, ó lè máa ṣe wá bíi pé Jèhófà ò tètè dáhùn àdúrà náà. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àdúrà wa ni Jèhófà máa ń dáhùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? Ó mọ̀ pé ìgbàgbọ́ tá a ní ló mú ká máa gbàdúrà sí òun. (Héb. 11:6) Tá a bá gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó máa fẹ́ rí i pé àwa náà ń sapá láti máa fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. (1 Jòh. 3:22) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká jáwọ́ nínú ìwà kan tí ò dáa, àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yẹra fún ohun tó lè mú ká tún hùwà náà, ká má sì jẹ́ kó sú wa. Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé kì í ṣe gbogbo àdúrà wa ni Jèhófà máa dáhùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó wá gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín; torí gbogbo ẹni tó bá ń béèrè máa rí gbà, gbogbo ẹni tó bá ń wá kiri máa rí, gbogbo ẹni tó bá sì ń kan ilẹ̀kùn la máa ṣí i fún.”—Mát. 7:7, 8. w21.08 8 ¶1; 10 ¶9-10
Thursday, July 27
Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ronú lé e lórí.—Sm. 119:97.
Ó yẹ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa lè túbọ̀ lágbára. (Jóṣ. 1:8) Tún kíyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ṣẹ àti bí àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣe bára mu látòkèdélẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ wa tó sì jẹ́ ọlọgbọ́n ló dá wa, òun náà ló sì mí sí àwọn tó kọ Bíbélì. (2 Tím. 3:14; 2 Pét. 1:21) Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kíyè sí àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tó wà nínú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti kìlọ̀ pé ó léwu téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ owó àti pé ìfẹ́ owó máa ń fa “ìrora tó pọ̀.” (1 Tím. 6:9, 10; Òwe 28:20; Mát. 6:24) Torí náà, ìkìlọ̀ tí Bíbélì fún wa pé ká má ṣe nífẹ̀ẹ́ owó bọ́gbọ́n mu gan-an. Ṣé o lè ronú àwọn ìlànà Bíbélì míì tó ti ṣe ẹ́ láǹfààní? Tá a bá ronú nípa àwọn ìmọ̀ràn tó ń ṣe wá láǹfààní tó wà nínú Bíbélì, àá rí i pé Ẹlẹ́dàá wa nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọ ohun tó dáa jù fún wa. Torí náà, á rọrùn fún wa láti gbẹ́kẹ̀ lé e. (Jém. 1:5) Ìyẹn á sì jẹ́ káyé wa túbọ̀ nítumọ̀.—Àìsá. 48:17, 18. w21.08 17-18 ¶12-13
Friday, July 28
Torí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.—Héb. 6:10.
Tó bá jẹ́ pé o ti ń dàgbà, o ò sì lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà rántí gbogbo iṣẹ́ rere tó o ti ṣe sẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, o ti fìtara ṣiṣẹ́ ìwàásù. Yàtọ̀ síyẹn, o ti fara da onírúurú ìṣòro títí kan àwọn èyí tó gba omijé lójú ẹ, síbẹ̀ o jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ojúṣe pàtàkì lo ti bójú tó nínú ètò Ọlọ́run, o sì ti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Kò mọ síbẹ̀ o, o tún ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ bí àwọn ìyípadà ṣe ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run. Bákan náà, ò ń fún àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún níṣìírí kí wọ́n lè máa báṣẹ́ wọn nìṣó. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì mọyì bó o ṣe jẹ́ adúróṣinṣin. Ó ṣèlérí pé òun ò “ní kọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin [òun] sílẹ̀”! (Sm. 37:28) Ó tún ṣèlérí pé: “Títí irun rẹ fi máa funfun, mi ò ní yéé gbé ọ.” (Àìsá. 46:4) Torí náà, má ṣe ronú pé o ò wúlò mọ́ nínú ètò Ọlọ́run torí pé o ti dàgbà. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o wúlò, o sì ṣeyebíye gan-an! w21.09 3 ¶4
Saturday, July 29
Jèhófà ń ṣàánú àwọn tó bẹ̀rù rẹ.—Sm. 103:13.
Jèhófà máa ń fàánú hàn torí pé ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n tó wá láti òkè . . . máa ń ṣàánú gan-an, ó sì ń so èso rere.” (Jém. 3:17) Bíi ti òbí kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, Jèhófà mọ̀ pé tóun bá ṣàánú wa, ó máa ṣe wá láǹfààní. (Àìsá. 49:15) Àánú tí Jèhófà fi hàn sí wa ló mú ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé báyìí. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ ọlọgbọ́n, ó máa ń fàánú hàn tó bá rí i pé ìdí wà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé Jèhófà kì í gba ìgbàkugbà láyè. Torí pé ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kò ní torí pé òun fẹ́ fàánú hàn, kó wá gba ìgbàkugbà láyè. Ká sọ pé ìránṣẹ́ Jèhófà kan wá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ìwà burúkú dàṣà, kí la máa ṣe? Ẹ̀mí Ọlọ́run darí Pọ́ọ̀lù láti sọ pé ká “jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú” irú ẹni bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́r. 5:11) Wọ́n máa ń yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. Ìgbésẹ̀ yìí ṣe pàtàkì, ká lè dáàbò bo àwọn ará tó jẹ́ olóòótọ́, kí ìjọ sì lè wà ní mímọ́. w21.10 9-10 ¶7-8
Sunday, July 30
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.—2 Kọ́r. 9:7.
Tá a bá ń fi ọrẹ ṣètìlẹyìn, à ń jọ́sìn Jèhófà nìyẹn. Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń ṣe àjọyọ̀, Jèhófà ò retí pé kí wọ́n wá síwájú òun lọ́wọ́ òfo. (Diu. 16:16) Ohun tí agbára kálukú wọn bá gbé ni Jèhófà retí pé kí wọ́n mú wá. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á fi hàn pé àwọn mọyì gbogbo nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún wọn. Báwo làwa náà ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì mọyì gbogbo ohun tó ń ṣe fún wa? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa fi ọrẹ ṣètìlẹyìn fún ìnáwó ìjọ àti iṣẹ́ kárí ayé bí agbára wa bá ṣe gbé e tó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Tó bá ti jẹ́ pé ó yá èèyàn lára, á túbọ̀ ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ìyẹn tó bá jẹ́ ohun tí èèyàn ní ló fi ṣe é, kì í ṣe ohun tí èèyàn kò ní.” (2 Kọ́r. 8:4, 12) Torí náà, inú Jèhófà máa ń dùn tó bá ń rí i pé ohun tá a fi ṣètọrẹ wá látọkàn wa, bó tiẹ̀ kéré.—Máàkù 12:42-44. w22.03 24 ¶13
Monday, July 31
Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́, ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo èèyàn.—1 Tẹs. 5:14.
Àwọn alàgbà ò lè yanjú gbogbo ìṣòro táwa èèyàn Jèhófà ní. Síbẹ̀, Jèhófà fẹ́ káwọn alàgbà ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti fún àwọn ará níṣìírí, kí wọ́n sì dáàbò bò wọ́n. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ àwọn alàgbà máa ń dí, báwo ni wọ́n ṣe lè máa wáyè láti ran àwọn ará lọ́wọ́ lásìkò tí wọ́n nílò ẹ̀ gan-an? Ẹ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Gbogbo ìgbà ni Pọ́ọ̀lù máa ń gbóríyìn fáwọn ará tó sì máa ń fún wọn níṣìírí. Ẹ̀yin alàgbà máa fi hàn pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù tẹ́ ẹ bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará tẹ́ ẹ sì ń finúure hàn sí wọn. (1 Tẹs. 2:7) Pọ́ọ̀lù fi dá àwọn ará lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, Jèhófà náà sì nífẹ̀ẹ́ wọn. (2 Kọ́r. 2:4; Éfé. 2:4, 5) Pọ́ọ̀lù mú àwọn ará ìjọ lọ́rẹ̀ẹ́, ó sì máa ń wà pẹ̀lú wọn. Pọ́ọ̀lù sọ àwọn nǹkan tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní fáwọn ará, ìyẹn sì fi hàn pé ó fọkàn tán wọn. (2 Kọ́r. 7:5; 1 Tím. 1:15) Síbẹ̀, bí Pọ́ọ̀lù ṣe máa ran àwọn ará lọ́wọ́ ló gbà á lọ́kàn, kì í ṣe bó ṣe máa yanjú àwọn ìṣòro tiẹ̀. w22.03 28 ¶9-10