ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es23 ojú ìwé 77-87
  • August

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • August
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2023
  • Ìsọ̀rí
  • Tuesday, August 1
  • Wednesday, August 2
  • Thursday, August 3
  • Friday, August 4
  • Saturday, August 5
  • Sunday, August 6
  • Monday, August 7
  • Tuesday, August 8
  • Wednesday, August 9
  • Thursday, August 10
  • Friday, August 11
  • Saturday, August 12
  • Sunday, August 13
  • Monday, August 14
  • Tuesday, August 15
  • Wednesday, August 16
  • Thursday, August 17
  • Friday, August 18
  • Saturday, August 19
  • Sunday, August 20
  • Monday, August 21
  • Tuesday, August 22
  • Wednesday, August 23
  • Thursday, August 24
  • Friday, August 25
  • Saturday, August 26
  • Sunday, August 27
  • Monday, August 28
  • Tuesday, August 29
  • Wednesday, August 30
  • Thursday, August 31
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2023
es23 ojú ìwé 77-87

August

Tuesday, August 1

Baba, dárí jì wọ́n.​—Lúùkù 23:34.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Róòmù tó kan ìṣó mọ́ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Jésù ni Jésù ní lọ́kàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ìkà ni wọ́n hù sí i, kò bínú tàbí kó máa dá àwọn tó pa á lẹ́bi. (1 Pét. 2:23) Bíi ti Jésù, a gbọ́dọ̀ múra tán láti máa dárí ji àwọn èèyàn. (Kól. 3:13) Àwọn èèyàn kan tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè máa ta kò wá torí pé ohun tá a gbà gbọ́ ò yé wọn àti pé ìwà wa yàtọ̀ sí tiwọn. Wọ́n lè parọ́ mọ́ wa, kí wọ́n dójú tì wá níṣojú àwọn míì, kí wọ́n da àwọn ìwé wa nù tàbí kí wọ́n tiẹ̀ halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn á lù wá. Dípò ká máa bínú sí wọn, a lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ káwọn tó ń ta kò wá lóye òtítọ́. (Mát. 5:44, 45) Nígbà míì, ó lè ṣòro fún wa láti dárí jì wọ́n, pàápàá tó bá jẹ́ pé wọ́n hùwà ìkà sí wa. Àmọ́ tá a bá kọ̀ tá ò dárí jì wọ́n, ó lè ṣàkóbá fún wa. (Sm. 37:8) Tá a bá ń dárí jini, ìyẹn fi hàn pé a ò jẹ́ kí ohun táwọn èèyàn ṣe sí wa mú ká máa bínú, a sì fẹ́ kọ́rọ̀ náà tán nínú wa.​—Éfé. 4:31, 32. w21.04 8-9 ¶3-4

Wednesday, August 2

Ẹ wo iye ìgbà tí wọ́n . . . bà á nínú jẹ́.​—Sm. 78:40.

Ṣé wọ́n ti yọ ẹnì kan nínú ìdílé ẹ lẹ́gbẹ́ rí? Ká sòótọ́, ó máa ń dunni gan-an. Ẹ wo bó ṣe máa dun Jèhófà tó nígbà táwọn áńgẹ́lì kan kẹ̀yìn sí i. (Júùdù 6) Ẹ tún wo bó ṣe máa ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ tó nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí i léraléra. (Sm. 78:41) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó máa ń dun Baba wa ọ̀run tí ẹnì kan tó o nífẹ̀ẹ́ bá fi òtítọ́ sílẹ̀. Ó mọ bí ẹ̀dùn ọkàn ẹ ṣe pọ̀ tó, ó sì dájú pé á dúró tì ẹ́, á sì fún ẹ lókun kó o lè fara dà á. Tí ọmọ kan bá fi Jèhófà sílẹ̀, àwọn òbí sábà máa ń ronú pé ohun kan wà tó yẹ káwọn ṣe táwọn ò ṣe. Arákùnrin kan sọ pé: “Lẹ́yìn tọ́rọ̀ yẹn ṣẹlẹ̀, mo máa ń dá ara mi lẹ́bi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lálàákálàá.” Arábìnrin kan tírú ẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí sọ pé: “Ṣé kì í ṣe pé èmi ni mi ò tọ́ ọmọ mi dáadáa ṣá? Kò jọ pé mo kọ́ ọ kí òtítọ́ lè jinlẹ̀ nínú ẹ̀ débi táá fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.” w21.09 26 ¶1-2, 4

Thursday, August 3

Wọ́n mọ̀ pé wọn ò kàwé àti pé wọ́n jẹ́ gbáàtúù.​—Ìṣe 4:13.

Àwọn kan ronú pé a ò tóótun láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí pé a ò gboyè jáde nílé ẹ̀kọ́ àwọn pásítọ̀. Àmọ́ ó ṣe pàtàkì kí wọ́n ṣèwádìí kí wọ́n lè mohun tó jóòótọ́ nípa wa. Ohun tí Lúùkù tó kọ ọ̀kan lára àwọn Ìwé Ìhìn Rere ṣe nìyẹn. Ó rí i dájú pé òun “wádìí ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ lọ́nà tó péye.” Ó fẹ́ káwọn tó ń kàwé rẹ̀ mọ bí ohun tí wọ́n gbọ́ nípa Jésù “ṣe jẹ́ òótọ́ tó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Lúùkù 1:1-4) Àwọn Júù tó wà ní Bèróà náà ṣe bíi ti Lúùkù. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere nípa Jésù, wọ́n lọ yẹ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù wò kí wọ́n lè mọ̀ bóyá òótọ́ lohun táwọn gbọ́. (Ìṣe 17:11) Lọ́nà kan náà, ó yẹ káwọn èèyàn máa ṣèwádìí dáadáa. Ó yẹ kí wọ́n ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kí wọ́n lè rí i dájú pé òótọ́ lohun táwa èèyàn Ọlọ́run fi ń kọ́ni. Ó tún yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa ìtàn àwa èèyàn Jèhófà lóde òní. Tí wọ́n bá fara balẹ̀ ṣe àwọn ìwádìí yìí, ohun táwọn èèyàn ń sọ kò ní mú wọn kọsẹ̀. w21.05 3 ¶7-8

Friday, August 4

Ẹ ṣí ọkàn yín sílẹ̀ pátápátá.​—2 Kọ́r. 6:13.

Ṣé ẹnì kan wà ní ìjọ yín tẹ́ ẹ lè ṣe lálejò nílé yín? Àwọn ìgbà kan wà tínú àwọn ará wa máa dùn gan-an tá a bá wà pẹ̀lú wọn. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń ṣòro fáwọn kan láti wà nílé nígbà táwọn mọ̀lẹ́bí wọn bá ń ṣọdún. Inú àwọn míì sì máa ń bà jẹ́ gan-an ní àyájọ́ ọjọ́ téèyàn wọn kan kú. Torí náà, tá a bá ń wà pẹ̀lú àwọn ará wa nírú àwọn àsìkò yìí, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn látọkàn wá. (Fílí. 2:20) Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kí Kristẹni kan ronú pé òun ò rẹ́ni fojú jọ tàbí pé òun dá wà. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń lo àwọn ará wa láti pèsè ohun tá a nílò. (Mát. 12:48-50) Àwa náà lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Torí náà, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà tàbí pé o ò rẹ́ni fojú jọ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú ẹ, kò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé! w21.06 13 ¶18-20

Saturday, August 5

Ẹ jẹ́ oníwà rere láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, kó lè jẹ́ pé tí wọ́n bá fẹ̀sùn ìwà ibi kàn yín, wọ́n á lè fojú ara wọn rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì torí ẹ̀ yin Ọlọ́run lógo.​—1 Pét. 2:12.

Jésù ò ṣíwọ́ àtimáa wàásù bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ò tẹ́tí sí i. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn èèyàn mọ òtítọ́, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó mọ̀ pé àwọn kan tí wọn ò tẹ́tí sí òun nígbà yẹn ṣì máa pa dà nígbàgbọ́ nínú òun. Bọ́rọ̀ àwọn àbúrò ẹ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ní gbogbo ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó fi wàásù, kò sí ìkankan lára wọn tó di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Jòh. 7:5) Àmọ́ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, wọ́n di Kristẹni. (Ìṣe 1:14) A ò mọ ẹni tó ṣì máa wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó sì máa di ìránṣẹ́ Jèhófà. Ó lè pẹ́ káwọn kan tó gbà pé òtítọ́ la fi ń kọ́ni kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀. Kódà, àwọn tí ò fetí sí wa lè kíyè sí ìwà rere wa kí wọ́n sì wá “yin Ọlọ́run lógo” nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. w21.05 18 ¶17-18

Sunday, August 6

Bí ẹ ṣe ń lọ, ẹ máa wàásù pé: “Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.”​—Mát. 10:7.

Nígbà tí Jésù wà láyé, iṣẹ́ alápá méjì ló fún àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Ó ní kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó sì sọ bí wọ́n ṣe máa ṣe é. (Lúùkù 8:1) Lára ohun tí Jésù sọ fún wọn ni pé àwọn kan á tẹ́tí sí wọn, àwọn míì ò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 9:2-5) Kódà, ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí iṣẹ́ náà ṣe máa gbòòrò tó, ó sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa jẹ́rìí “fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:14; Ìṣe 1:8) Ó tún sọ fún wọn pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn tó máa di ọmọlẹ́yìn òun láti máa pa gbogbo ohun tí òun pa láṣẹ fún wọn mọ́. Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà náà máa tẹ̀ síwájú títí di ọjọ́ wa yìí, àní “títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:18-20) Bákan náà, nínú ìran tí Jésù fi han Jòhánù, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn òun ló yẹ kó máa kọ́ àwọn èèyàn nípa ­Jèhófà.​—Ìfi. 22:17. w21.07 2-3 ¶3-4

Monday, August 7

Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di agbéraga, kí a má ṣe máa bá ara wa díje, kí a má sì máa jowú ara wa.​—Gál. 5:26.

Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ yọrí ọlá ju àwọn míì lọ, kò sì sí ohun tí wọn ò lè ṣe torí pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀. Oníṣòwò kan lè máa dá ọgbọ́nkọ́gbọ́n kí ilé iṣẹ́ ẹ̀ lè gbayì ju tàwọn míì lọ. Agbábọ́ọ̀lù kan lè mọ̀ọ́mọ̀ ṣe agbábọ́ọ̀lù míì tó wà nínú ẹgbẹ́ tí wọ́n ń bá díje léṣe kí ẹgbẹ́ tiẹ̀ lè borí. Akẹ́kọ̀ọ́ kan lè jíwèé wò kó lè yege ìdánwò láti wọ yunifásítì kan tó lóókọ. Àwa Kristẹni mọ̀ pé irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ò dáa torí pé wọ́n jẹ́ apá kan “iṣẹ́ ti ara.” (Gál. 5:19-21) Àmọ́, ṣé ó ṣeé ṣe káwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn díje nínú ìjọ láìfura? Ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì torí pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ lè da ìjọ rú, kó sì mú káwọn ará kẹ̀yìn síra wọn. Á dáa ká ronú lórí àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ tó wà nínú Bíbélì tí wọn ò bá ara wọn díje. w21.07 14 ¶1-2

Tuesday, August 8

Aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń ro ti àwọn aláìní; Jèhófà yóò gbà á sílẹ̀ ní ọjọ́ àjálù.​—Sm. 41:1.

Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ló ń mú ká ṣèrànwọ́ fáwọn tíṣòro dé bá. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin onínúure lóde òní máa ń dúró ti àwọn ará ìjọ tíṣòro dé bá. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, wọ́n sì ṣe tán láti ṣe ohunkóhun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 12:25, àlàyé ìsàlẹ̀; 24:10) Ohun tí wọ́n ṣe yìí bá ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù sọ mu pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́, ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo èèyàn.” (1 Tẹs. 5:14) Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà ran arákùnrin tàbí arábìnrin kan lọ́wọ́ ni pé ká máa tẹ́tí sí i tó bá ń sọ̀rọ̀, ká sì fi dá a lójú pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Jèhófà mọyì ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí tá a bá ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ṣeyebíye lójú rẹ̀. Òwe 19:17 sọ pé: “Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan, á sì san án pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.” w21.11 10 ¶11-12

Wednesday, August 9

Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé ẹni rere ni Jèhófà, aláyọ̀ ni ọkùnrin tí ó fi í ṣe ibi ààbò.​—Sm. 34:8.

Kí làwọn nǹkan tá a lè ṣe báyìí ká lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú? Ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ káwọn ohun tá a ní báyìí tẹ́ wa lọ́rùn, àmọ́ ká rí i dájú pé àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà lohun tó ń fún wa láyọ̀ jù lọ. Ìdí ni pé bá a ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà, tí àárín wa pẹ̀lú rẹ̀ sì gún régé, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ dá wa lójú pé ó máa dá wa nídè nígbà tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá gbéjà kò wá. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní jẹ́ ká rí ìdí tí Dáfídì fi gbà pé Jèhófà ò ní fòun sílẹ̀ láé. Ó sábà máa ń gbára lé Jèhófà, Jèhófà náà ò sì já a kulẹ̀. Nígbà tí Dáfídì wà ní kékeré, ó kojú Gòláyátì tó jẹ́ àkòtagìrì olórí ogun Filísínì, ó sì sọ fún un pé: “Lónìí yìí, Jèhófà yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́.” (1 Sám. 17:46) Nígbà tó yá, Dáfídì di ìránṣẹ́ Ọba Sọ́ọ̀lù, àwọn ìgbà kan sì wà tí Sọ́ọ̀lù ń wá bó ṣe máa pa á. Àmọ́ “Jèhófà wà pẹ̀lú” Dáfídì. (1 Sám. 18:12) Bí Dáfídì ṣe rí ọwọ́ Jèhófà nígbèésí ayé ẹ̀ yìí mú kó dá a lójú pé Jèhófà ò ní fi òun sílẹ̀ láé, kò sì ní dá òun dá ìṣòro òun. w22.01 6 ¶14-15

Thursday, August 10

Gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í hó yèè, wọ́n sì ń yìn ín.​—Jóòbù 38:7.

Jèhófà máa ń fi sùúrù ṣe gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè mú ìyìn àti ògo wá fún orúkọ rẹ̀, kó sì ṣe àwọn míì náà láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe dá ayé yìí ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé káwa èèyàn lè gbádùn rẹ̀. Nígbà tí Bíbélì ń ṣàlàyé nípa ẹ̀, ó sọ pé ó “díwọ̀n rẹ̀,” ó ri “àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀,” ó sì fi “òkúta igun ilé rẹ̀” lélẹ̀. (Jóòbù 38:5, 6) Kódà, Jèhófà lo àkókò láti yẹ ohun tó ń ṣe wò. (Jẹ́n. 1:10, 12) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára àwọn áńgẹ́lì bí wọ́n ṣe ń rí gbogbo ohun tí Jèhófà ń dá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ó dájú pé inú wọn máa dùn gan-an. Kódà, ìgbà kan wà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ‘hó yèè, tí wọ́n sì ń yìn ín.’ Kí la rí kọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gba ọ̀pọ̀ ọdún kí Jèhófà tó parí gbogbo ohun tó dá, síbẹ̀ lẹ́yìn tó yẹ gbogbo ẹ̀ wò, ó sọ pé “ó dára gan-an.”​—Jẹ́n. 1:31. w21.08 9 ¶6-7

Friday, August 11

O káre láé, ẹrú rere àti olóòótọ́!​—Mát. 25:23.

Jésù sọ àpèjúwe ọkùnrin kan tó fẹ́ rìnrìn àjò. Kó tó lọ, ó pe àwọn ẹrú rẹ̀, ó sì fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní tálẹ́ńtì pé kí wọ́n fi ṣòwò. Ọkùnrin náà fún wọn ní owó bí agbára ẹrú kọ̀ọ̀kan ṣe mọ. Ó fún ọ̀kan ní tálẹ́ńtì márùn-ún, ó fún èkejì ní tálẹ́ńtì méjì, ó sì fún ẹ̀kẹta ní tálẹ́ńtì kan. Àwọn ẹrú méjì àkọ́kọ́ ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè jèrè owó púpọ̀ sí i fún ọ̀gá wọn. Àmọ́ ẹrú kẹta ò fi tálẹ́ńtì tí ọ̀gá rẹ̀ fún un ṣòwò, ìyẹn sì mú kí ọ̀gá rẹ̀ lé e dà nù. Ẹrú àkọ́kọ́ àti ẹrú kejì gbà pé iṣẹ́ pàtàkì ni ọ̀gá àwọn gbé fún àwọn, torí náà wọ́n ṣiṣẹ́ kára, wọ́n jèrè tálẹ́ńtì sí i, inú ọ̀gá wọn sì dùn sí wọn. Láfikún síyẹn, ó yìn wọ́n, ó sì fún wọn láwọn ­ojúṣe míì. w21.08 21 ¶7; 22 ¶9-10

Saturday, August 12

Lẹ́ẹ̀kan sí i, màá mi ọ̀run àti ayé.​—Hág. 2:6.

Jèhófà ti mú sùúrù gan-an láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ìdí sì ni pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run. (2 Pét. 3:9) Ó ti fún gbogbo èèyàn láǹfààní láti yí pa dà. Àmọ́, sùúrù ẹ̀ máa dópin lọ́jọ́ kan. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Fáráò nígbà ayé Mósè ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tí ò bá yí pa dà lónìí. Jèhófà sọ fún Fáráò pé: “Mi ò bá ti na ọwọ́ mi kí n lè fi àjàkálẹ̀ àrùn tó le gan-an kọ lu ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ, kí n sì pa ọ́ rẹ́ kúrò ní ayé. Àmọ́ ìdí tí mo fi dá ẹ̀mí rẹ sí ni pé: kí n lè fi agbára mi hàn ọ́, kí a sì lè ròyìn orúkọ mi ní gbogbo ayé.” (Ẹ́kís. 9:15, 16) Gbogbo orílẹ̀-­èdè ló máa wá gbà láìjanpata pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run tòótọ́. (Ìsík. 38:23) Ìmìtìtì tí ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ yìí máa yọrí sí ìparun ayérayé fáwọn tí ò fara mọ́ Ìjọba Jèhófà bíi ti Fáráò. w21.09 18-19 ¶17-18

Sunday, August 13

Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.​—Róòmù 12:15.

Ṣé ó dùn ẹ́ gan-an nígbà tí wọ́n yọ èèyàn ẹ kan tó o fẹ́ràn lẹ́gbẹ́? Ká wá sọ pé láìmọ̀ àwọn kan nínú ìjọ sọ ohun tó tún dá kún ẹ̀dùn ọkàn ẹ ńkọ́, kí lo lè ṣe? Ohun kan ni pé, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa sọ ohun táá mú kára tù ẹ́. (Jém. 3:2) Torí pé aláìpé ni gbogbo wa, má jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu pé àwọn kan lè má mọ ohun tí wọ́n máa sọ tàbí káwọn míì tiẹ̀ sọ ohun tó máa dùn ẹ́ láìmọ̀. Rántí ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa, pé: “Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà, kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì.” (Kól. 3:13) Ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti dúró ti ìdílé ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́. Àsìkò yìí gan-an ni wọ́n nílò ìfẹ́ àti ìṣírí látọ̀dọ̀ àwọn ará. (Héb. 10:24, 25) Nígbà míì, ìdílé àwọn tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ máa ń ronú pé àwọn kan nínú ìjọ máa ń yẹra fún àwọn, wọ́n sì máa ń hùwà bíi pé gbogbo ìdílé àwọn ni wọ́n yọ lẹ́gbẹ́. A ò gbọ́dọ̀ ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n nírú èrò bẹ́ẹ̀ láé! Ní pàtàkì, a gbọ́dọ̀ máa gbóríyìn fáwọn ọ̀dọ́ táwọn òbí wọn ti fi òtítọ́ sílẹ̀, ká sì máa fún wọn ­níṣìírí. w21.09 29 ¶13-14; 30 ¶16

Monday, August 14

Ọlọ́gbọ́n máa ń fetí sílẹ̀, á sì kọ́ ẹ̀kọ́ sí i.​—Òwe 1:5.

Tí àgbàlagbà kan àti ọ̀dọ́ kan bá jọ ń sọ̀rọ̀, àwọn méjèèjì ló máa jàǹfààní. (Róòmù 1:12) Á túbọ̀ dá ọ̀dọ́ yẹn lójú pé Jèhófà máa ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Àgbàlagbà náà á sì mọ̀ pé àwọn ará nífẹ̀ẹ́ òun, wọ́n sì mọyì òun. Inú àgbàlagbà náà á túbọ̀ máa dùn bó ṣe ń sọ àwọn ìbùkún tó ti rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Ẹwà ojú kì í tọ́jọ́, àmọ́ àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà máa ń lẹ́wà sí i bọ́dún ṣe ń gorí ọdún. (1 Tẹs. 1:2, 3) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, wọ́n ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí àwọn, wọ́n sì ń jẹ́ kó ran àwọn lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe tó yẹ. Bá a bá ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ará wa tó ti dàgbà, tá à ń bọlá fún wọn, tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa kà wọ́n sí ẹni ọ̀wọ́n bíi ti Jèhófà! Kí ìjọ tó lè wà níṣọ̀kan, kì í ṣe àwọn ọ̀dọ́ nìkan ló yẹ kó mọyì àwọn àgbàlagbà, ó yẹ káwọn àgbàlagbà náà mọyì àwọn ọ̀dọ́. w21.09 7 ¶15-18

Tuesday, August 15

Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; torí bí ẹ bá ṣe dáni lẹ́jọ́ la ṣe máa dá yín lẹ́jọ́.​—Mát. 7:1, 2.

Ó yẹ ká ṣọ́ra ká má lọ máa fọwọ́ tó le jù mú àwọn èèyàn. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká fìwà jọ Ọlọ́run wa ẹni tí “àánú rẹ̀ pọ̀.” (Éfé. 2:4) Kéèyàn jẹ́ aláàánú kọjá kí àánú ẹni tó ń jìyà kàn máa ṣèèyàn. Ó tún gba pé kéèyàn ṣe nǹkan kan láti ran ẹni náà lọ́wọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fara balẹ̀ kíyè sí àwọn tá a lè ràn lọ́wọ́ nínú ìdílé wa, nínú ìjọ wa àti ládùúgbò wa. Ká sòótọ́, onírúurú ọ̀nà la lè gbà fàánú hàn. Ṣé a lè tu ẹnì kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú? Ṣé a lè ṣe àwọn nǹkan pàtó láti ran ẹnì kan lọ́wọ́, bóyá ká gbé oúnjẹ lọ fún un tàbí ká ràn án lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì? Ṣé a lè mú Kristẹni kan tí wọ́n gbà pa dà lọ́rẹ̀ẹ́, ká lè máa tù ú nínú? Ṣé a lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn? (Jóòbù 29:12, 13; Róòmù 10:14, 15; Jém. 1:27) Tá a bá ń kíyè sí àwọn tó nírú ìṣòro bẹ́ẹ̀, àá rí àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fàánú hàn sí wọn. Tá a bá ń fàánú hàn, ó dájú pé àá múnú Jèhófà Baba wa ọ̀run dùn, ẹni tí “àánú rẹ̀ pọ̀.” w21.10 13 ¶20-22

Wednesday, August 16

Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní.​—Sm. 23:1.

Ní Sáàmù 23, Dáfídì sọ àwọn nǹkan tó ṣeyebíye jù lọ, ìyẹn àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣe fún un torí pé ó gbà kí Jèhófà máa bójú tó òun. Jèhófà darí Dáfídì “ní ipa ọ̀nà òdodo,” ó sì dúró tì í nígbà dídùn àti nígbà kíkan. Dáfídì mọ̀ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé “ibi ìjẹko tútù” ni Jèhófà mú kóun dùbúlẹ̀ sí, òun ò bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro. Àwọn ìgbà kan wà tó rẹ̀wẹ̀sì, bí ìgbà tó ń rìn “nínú àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri,” bẹ́ẹ̀ ló tún ní àwọn ọ̀tá. Àmọ́ Dáfídì ò “bẹ̀rù ewukéwu” torí pé Jèhófà ló ń bójú tó o. Kí ló fi hàn pé Dáfídì ò “ṣaláìní ohun rere”? Dáfídì ní gbogbo ohun tó nílò táá jẹ́ kí àjọṣe àárín òun àti Jèhófà túbọ̀ gún régé. Kì í ṣe àwọn nǹkan tara ló mú kó máa láyọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí ìwọ̀nba nǹkan tí Jèhófà fún òun tẹ́ òun lọ́rùn. Ohun tó jẹ Dáfídì lógún ni bó ṣe máa rí ojúure Jèhófà àti ààbò rẹ̀. Ohun tí Dáfídì sọ jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra káwọn nǹkan tara má lọ gbà wá lọ́kàn jù. w22.01 3-4 ¶5-7

Thursday, August 17

Ẹnì kọ̀ọ̀kan máa gba èrè iṣẹ́ tirẹ̀.​—1 Kọ́r. 3:8.

Nígbà àtijọ́, àwọn èèyàn ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Nóà jẹ́ “oníwàásù òdodo,” ọ̀pọ̀ ọdún ló sì fi wàásù. (2 Pét. 2:5) Ó dájú pé ó retí káwọn èèyàn tẹ́tí gbọ́ ìwàásù òun, àmọ́ Jèhófà ò sọ pé àwọn èèyàn máa gbọ́ tàbí wọn ò ní gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí Ọlọ́run sọ fún Nóà nípa bó ṣe máa kan ọkọ̀ áàkì, ohun tó sọ ni pé: “Kí o wọ inú áàkì náà, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti ìyàwó rẹ pẹ̀lú ìyàwó àwọn ọmọ rẹ.” (Jẹ́n. 6:18) Ọkọ̀ tí Ọlọ́run ní kí Nóà kàn kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi, kò sì lè gba èèyàn púpọ̀. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí Nóà rò pé àwọn èèyàn tó máa gbọ́ ìwàásù òun ò ní pọ̀. (Jẹ́n. 6:15) Bá a sì ṣe mọ̀, kò sẹ́nì kankan nínú ayé ìgbà yẹn tó gbọ́ ìwàásù Nóà. (Jẹ́n. 7:7) Ṣé Jèhófà wá sọ pé Nóà ò ṣàṣeyọrí? Rárá o! Lójú Ọlọ́run, Nóà ṣàṣeyọrí, inú Jèhófà sì dùn sí i torí ó ṣiṣẹ́ náà ­tọkàntọkàn.​—Jẹ́n. 6:22. w21.10 26 ¶10-11

Friday, August 18

Ọwọ́ mi kún nígbà tí mo lọ, àmọ́ Jèhófà mú kí n pa dà lọ́wọ́ òfo.​—Rúùtù 1:21.

Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Rúùtù nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Náómì sọ yìí. Rúùtù ti ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ran Náómì lọ́wọ́. Rúùtù sunkún pẹ̀lú rẹ̀, ó tù ú nínú, ọ̀pọ̀ ọjọ́ sì ni wọ́n fi jọ rìnrìn àjò pa dà sílé. Láìka gbogbo ohun tí Rúùtù ṣe yìí sí, Náómì sọ pé: “Jèhófà mú kí n pa dà lọ́wọ́ òfo.” Ọ̀rọ̀ tí Náómì sọ yìí fi hàn pé kò mọyì gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí Rúùtù ṣe fún un. Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn máa dun Rúùtù gan-an. Àmọ́ kò fi Náómì sílẹ̀ rárá. (Rúùtù 1:3-18) Lónìí, arábìnrin kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn lè sọ ohun tó dùn wá bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣe ipa tiwa láti ràn án lọ́wọ́. Àmọ́, a ò ní jẹ́ kínú bí wa, ńṣe la máa dúró ti arábìnrin wa gbágbáágbá, àá sì bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè tù ú nínú. (Òwe 17:17) Arábìnrin kan tó wà nínú ìṣòro lè má kọ́kọ́ gbà ká ran òun lọ́wọ́, síbẹ̀ ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tá a ní sí i ò ní jẹ́ ká fi í sílẹ̀.​—Gál. 6:2. w21.11 11 ¶17-19

Saturday, August 19

Kí ẹ̀yin náà di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín.​—1 Pét. 1:15.

Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ìjẹ́mímọ́” sábà máa ń tọ́ka sí ìwà mímọ́ àti ohun mímọ́. Ó tún máa ń tọ́ka sí yíya ohun kan sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Lédè míì, a lè sọ pé ẹni mímọ́ ni wá tí ìwà wa bá mọ́, tá à ń jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà, tá a sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, tí Jèhófà sì jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà, síbẹ̀, ó ń wù ú pé ká jẹ́ ọ̀rẹ́ òun. Jèhófà jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà. Ohun táwọn séráfù, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì tó sún mọ́ ìtẹ́ Jèhófà sọ nípa rẹ̀ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀. Àwọn kan lára wọn sọ pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.” (Àìsá. 6:3) Èyí fi hàn pé káwọn áńgẹ́lì tó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run tó jẹ́ mímọ́, àwọn náà gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́. Ẹni mímọ́ sì ni wọ́n. w21.12 3 ¶4-5

Sunday, August 20

Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe bí aláìlọ́gbọ́n àmọ́ bí ọlọ́gbọ́n, kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.​—Éfé. 5:15, 16.

Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń ronú nípa ọ̀nà tó dáa jù lọ láti gbé ìgbé ayé wọn. Àmọ́, àwọn agbani-nímọ̀ràn níléèwé àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè máa rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n lọ sí yunifásítì kí wọ́n lè ríṣẹ́ táá máa mówó rẹpẹtẹ wọlé. Irú ẹ̀kọ́ ìwé bẹ́ẹ̀ lè gba ọ̀pọ̀ àkókò lọ́wọ́ wọn. Ṣùgbọ́n nínú ìjọ Kristẹni, àwọn òbí àtàwọn ọ̀rẹ́ máa ń rọ àwọn ọ̀dọ́ láti fi ìgbésí ayé wọn ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kí ló máa ran ọ̀dọ́ kan tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa jù? Á jàǹfààní tó pọ̀ gan-an tó bá ka ohun tó wà nínú Éfésù 5:15-17, tó sì ṣàṣàrò lé e lórí. Lẹ́yìn tí ọ̀dọ́ kan bá ti ka àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, ó lè bi ara ẹ̀ pé: ‘Kí ni “ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́”? Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí ìpinnu tí mo bá ṣe? Báwo ni ohun tí mo bá pinnu ṣe máa jẹ́ kí n lo àkókò mi lọ́nà tó dáa jù?’ Rántí pé “àwọn ọjọ́ burú” àti pé ayé tí Sátánì ń ṣàkóso yìí máa tó dópin. w22.01 27 ¶5

Monday, August 21

Ní tòótọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ ò gbà á gbọ́.​—Jòh. 7:5.

Ìgbà wo ni Jémíìsì di olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù? Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, “ó fara han Jémíìsì, lẹ́yìn náà, gbogbo àpọ́sítélì.” (1 Kọ́r. 15:7) Lẹ́yìn tí Jésù fara han Jémíìsì, ó di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Jémíìsì náà wà níbẹ̀ nígbà táwọn àpọ́sítélì fẹ́ gba ẹ̀mí mímọ́ nínú yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 1:13, 14) Nígbà tó yá, inú Jémíìsì dùn gan-an pé òun wà lára ìgbìmọ̀ olùdarí nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. (Ìṣe 15:6, 13-22; Gál. 2:9) Kó tó di ọdún 62 S.K., ẹ̀mí Ọlọ́run darí rẹ̀ láti kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Lẹ́tà yẹn ṣe wá láǹfààní lónìí bóyá ọ̀run la máa gbé tàbí ayé. (Jém. 1:1) Bí Josephus tó jẹ́ òpìtàn nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe sọ, Àlùfáà Àgbà àwọn Júù tó ń jẹ́ Ananáyà Kékeré ló pàṣẹ pé kí wọ́n pa Jémíìsì. Àmọ́, Jémíìsì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí tó fi parí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láyé. w22.01 8 ¶3; 9 ¶5

Tuesday, August 22

Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?​—Mát. 27:46.

Ẹ̀kọ́ kan tá a kọ́ nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní ni pé a ò gbọ́dọ̀ retí pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa dáàbò bò wá ká má bàa kojú àdánwò. Bí Jèhófà ṣe fàyè gba àwọn ọ̀tá láti dán Jésù wò dé góńgó, àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe tán láti jẹ́ olóòótọ́ kódà títí dójú ikú. (Mát. 16:24, 25) Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní jẹ́ kí wọ́n dán wa wò kọjá ohun tá a lè mú mọ́ra. (1 Kọ́r. 10:13) Ẹ̀kọ́ míì ni pé bíi ti Jésù, wọ́n lè fìyà jẹ wá láìṣẹ̀ láìrò. (1 Pét. 2:19, 20) Kì í ṣe torí pé a hùwà àìdáa ni wọ́n ṣe ń ta kò wá. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a kì í ṣe apá kan ayé, a sì ń jẹ́rìí sí òtítọ́. (Jòh. 17:14; 1 Pét. 4:15, 16) Jésù mọ ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba pé kóun jìyà. Àmọ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan béèrè ìbéèrè kí wọ́n lè mọ ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba àwọn nǹkan kan. (Háb. 1:3) Torí pé aláàánú àti onísùúrù ni Jèhófà, kò wò wọ́n bí ẹni tí ò nígbàgbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọ̀ pé ṣe ni wọ́n fẹ́ kí òun tu àwọn nínú.​—2 Kọ́r. 1:3, 4. w21.04 11 ¶9-10

Wednesday, August 23

Kí àdúrà mi dà bíi tùràrí tí a ṣètò sílẹ̀ níwájú rẹ.​—Sm. 141:2.

Inú Jèhófà máa dùn sí ìjọsìn wa tá a bá ń jọ́sìn ẹ̀ lọ́nà tó fẹ́, tá a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, tá a sì ń bọ̀wọ̀ fún un. A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, a sì mọ̀ pé òun ló yẹ ká máa jọ́sìn. Torí náà, ọ̀nà tó dáa jù la fẹ́ gbà jọ́sìn ẹ̀. Ọ̀kan lára ọ̀nà táà ń gbà jọ́sìn Jèhófà ni tá a bá ń gbàdúrà sí i. Bíbélì fi àdúrà táà ń gbà sí Jèhófà wé tùràrí tí wọ́n fara balẹ̀ ṣe, tí wọ́n ń lò nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì. Òórùn dídùn tí tùràrí náà máa ń ní máa ń múnú Jèhófà dùn. Lọ́nà kan náà, àdúrà àtọkànwá táà ń gbà sí Jèhófà “máa ń múnú” rẹ̀ dùn, kódà tí àdúrà náà ò bá tiẹ̀ gùn. (Òwe 15:8; Diu. 33:10) Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá gbàdúrà àtọkànwá sí i, tá a sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ torí àwọn nǹkan tó ti ṣe fún wa. Jèhófà fẹ́ ká máa sọ ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún òun, ohun tá a fẹ́ àtohun táà ń retí pé kó ṣe fún wa. Torí náà, kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, á dáa kó o kọ́kọ́ ronú nípa ohun tó o máa sọ. Tó o bá ṣẹ bẹ́ẹ̀, àdúrà tóò ń gbà sí Bàbá rẹ ọ̀run máa dà bíi “tùràrí” tó ń mú òórùn dídùn tó dáa jù lọ jáde. w22.03 20 ¶2; 21 ¶7

Thursday, August 24

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ní ìpọ́njú máa rí ìtura gbà pẹ̀lú wa nígbà ìfihàn Jésù Olúwa láti ọ̀run pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára.​—2 Tẹs. 1:7.

Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, àwa kọ́ la máa pinnu ẹni tí Jèhófà máa fàánú hàn sí àti ẹni tí kò ní fàánú hàn sí. (Mát. 25:34, 41, 46) Ṣé a máa fara mọ́ ìdájọ́ tí Jèhófà bá ṣe, àbí ṣé ìyẹn máa mú ká má sin Jèhófà mọ́? Torí náà, ó yẹ ká túbọ̀ fọkàn tán Jèhófà báyìí ká lè fọkàn tán an pátápátá lọ́jọ́ iwájú. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára wa nínú ayé tuntun nígbà tí ìsìn èké àtàwọn jẹgúdújẹrá oníṣòwò ò ní sí mọ́, títí kan àwọn olóṣèlú tó ti fi ìyà jẹ àwọn èèyàn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Kò ní sí àìsàn àti ọjọ́ ogbó mọ́, àwọn èèyàn wa náà ò sì ní kú mọ́. Jèhófà máa fi Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù sínú ẹ̀wọ̀n fún ẹgbẹ̀rún ọdún kan. Jèhófà sì máa ṣàtúnṣe gbogbo aburú tí wọ́n ti fà. (Ìfi. 20:2, 3) Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó nígbà yẹn pé a fara mọ́ ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan! w22.02 6-7 ¶16-17

Friday, August 25

Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá àlàáfíà.​—Mát. 5:9.

Èèyàn àlàáfíà ni Jésù. Bí àlàáfíà ṣe máa wà láàárín òun àtàwọn èèyàn ló ń wá, ó sì máa ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n yanjú aáwọ̀ tó bá wà láàárín wọn àtàwọn ẹlòmíì. Jésù kọ́ àwọn èèyàn pé wọ́n gbọ́dọ̀ yanjú aáwọ̀ pẹ̀lú arákùnrin wọn tí wọ́n bá fẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn. (Mát. 5:23, 24) Yàtọ̀ síyẹn, léraléra ni Jésù rọ àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé kí wọ́n yéé ṣe awuyewuye lórí ẹni tó tóbi jù láàárín wọn. (Lúùkù 9:46-48; 22:24-27) Ká tó lè jẹ́ ẹni àlàáfíà, ohun tá a máa ṣe kọjá ká kàn yẹra fún ohun tó lè dá aáwọ̀ sílẹ̀. Ó yẹ ká gbé ìgbésẹ̀ láti yanjú aáwọ̀, ká sì rọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa pé káwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀. (Fílí. 4:2, 3; Jém. 3:17, 18) Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ ohun kan wà tí mo lè yááfì kí àlàáfíà lè wà láàárín èmi àtàwọn èèyàn? Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣẹ̀ mí, ṣé mo máa ń dì í sínú? Ṣé mo máa ń fẹ́ kó jẹ́ pé òun ló máa kọ́kọ́ wá bá mi àbí èmi ni mo máa ń kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ láti yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín wa tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé òun ló ṣẹ̀ mí?’ w22.03 10 ¶10-11

Saturday, August 26

Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.​—Ìṣe 20:35.

Ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn máa “yọ̀ǹda ara wọn tinútinú” láti ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, Jésù Ọmọ rẹ̀ lá sì máa darí wọn. (Sm. 110:3) Ó dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti ń ṣẹ báyìí. Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù wákàtí làwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A kì í gba owó fún iṣẹ́ yìí, tọkàntọkàn la fi ń ṣe é. Bákan náà, a máa ń pèsè ohun táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nílò, a máa ń fún wọn níṣìírí, a sì máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára. Ọ̀pọ̀ wákàtí làwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń lò láti fi múra iṣẹ́ tí wọ́n ní nípàdé, tí wọ́n sì tún ń lò láti fi ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn ará. Kí ló ń mú ká ṣe gbogbo ohun táà ń ṣe yìí? Ìfẹ́ ni. Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà àtàwọn èèyàn ló ń mú ká ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 22:37-39) Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ ní ti pé ó máa ń gbọ́ tàwọn èèyàn ṣáájú tiẹ̀. A sì máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. (Róòmù 15:1-3) Ọ̀pọ̀ ìbùkún làwọn tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù máa gbà. w22.02 20 ¶1-2

Sunday, August 27

Owó iṣẹ́ alágbàṣe ò gbọ́dọ̀ wà lọ́wọ́ yín di àárọ̀ ọjọ́ kejì.​—Léf. 19:13.

Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe, wọ́n sì máa ń sanwó fún alágbàṣe lẹ́yìn iṣẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Tí wọn ò bá sanwó fún alágbàṣe kan, kò ní rówó tó fi máa bọ́ ìdílé ẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Torí náà, Jèhófà sọ fún wọn pé: “Aláìní ni, owó iṣẹ́ yìí ló sì ń gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró.” (Diu. 24:14, 15; Mát. 20:8) Lóde òní, ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n máa ń sanwó fún ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ lóṣù, kì í ṣe ojoojúmọ́. Síbẹ̀, ìlànà tó wà nínú Léfítíkù 19:13 ṣì wúlò lásìkò yìí. Àwọn kan tó gba àwọn èèyàn síṣẹ́ máa ń rẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ wọn jẹ torí owó tí wọ́n ń san fún wọn kéré gan-an. Kò sóhun táwọn òṣìṣẹ́ yìí lè ṣe sọ́rọ̀ náà àfi kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè rówó táṣẹ́rẹ́ tí wọ́n á fi máa jẹun. Ohun tí àwọn agbanisíṣẹ́ kan ń ṣe nìyẹn tá a fi lè sọ pé wọn kì í san ‘owó iṣẹ́ alágbàṣe.’ Kristẹni kan tó gba àwọn èèyàn síṣẹ́ gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òun ṣẹ̀tọ́ ­fáwọn òṣìṣẹ́ òun. w21.12 10 ¶9-10

Monday, August 28

Òùngbẹ ń gbẹ mí.​—Jòh. 19:28.

Ó dájú pé òùngbẹ ti ń gbẹ Jésù gan-an lẹ́yìn tí wọ́n fìyà jẹ ẹ́. Ìdí nìyẹn tó fi ní kí wọ́n fún òun lómi. Jésù gbà pé kò sóhun tó burú láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀. Torí náà, ó yẹ káwa náà máa sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa. Lọ́pọ̀ ìgbà, a kì í fẹ́ sọ ohun tó ń ṣe wá fáwọn míì, àmọ́ tọ́rọ̀ bá dójú ẹ̀, tá a sì rí i pé a nílò ìrànlọ́wọ́, kò yẹ ká dé ọ̀rọ̀ náà mọ́ra. Ó ṣe tán wọ́n ní téèyàn bá dákẹ́, tara ẹ̀ á bá a dákẹ́. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé àgbàlagbà ni wá tàbí pé ara wa ò yá, a lè bẹ ọ̀rẹ́ wa kan pé kó gbé wa lọ síbi tá a ti fẹ́ rajà tàbí ilé ìwòsàn. Tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, a lè fọ̀rọ̀ lọ alàgbà kan tàbí Kristẹni míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ kó lè fi “ọ̀rọ̀ rere” gbé wa ró. (Òwe 12:25) Rántí pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nífẹ̀ẹ́ ẹ, wọ́n sì ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní “ìgbà wàhálà.” (Òwe 17:17) Àmọ́, wọn ò lè rí ọkàn ẹ, wọn ò sì lè mọ̀ pé o nílò ìrànlọ́wọ́ àfi tó o bá sọ fún wọn. w21.04 11-12 ¶11-12

Tuesday, August 29

Tí o bá rẹ̀wẹ̀sì ní ọjọ́ wàhálà, agbára rẹ ò ní tó nǹkan.​—Òwe 24:10.

Kì í rọrùn fún ọ̀pọ̀ nínú wa tí nǹkan bá yí pa dà fún wa. Àwọn kan tó ti wà lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn fún ọ̀pọ̀ ọdún ti gba iṣẹ́ ìsìn míì báyìí. Àwọn míì sì ní láti fi iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọ sílẹ̀ torí pé wọ́n ti dàgbà. Inú wa kì í dùn tírú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Tó bá jẹ́ pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan làwa náà fi ń wò ó, ó máa rọrùn fún wa láti fara dà á tí nǹkan bá yí pa dà fún wa. Ọ̀pọ̀ nǹkan àgbàyanu ni Jèhófà ń ṣe lónìí, àǹfààní ńlá ló sì jẹ́ pé à ń bá a ṣiṣẹ́. (1 Kọ́r. 3:9) Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ò ní yí pa dà láé. Torí náà, táwọn àyípadà kan bá kàn ẹ́, má ṣe lo gbogbo àkókò ẹ láti máa ronú nípa ìdí tí àyípadà náà fi wáyé. Dípò tí wàá fi máa ronú ṣáá nípa àwọn “ọjọ́ àtijọ́,” ṣe ni kó o bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o rí àwọn nǹkan dáadáa nínú àyípadà náà. (Oníw. 7:10) Ẹ jẹ́ ká gbà pé nǹkan ṣì máa dáa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó kódà tí nǹkan bá yí pa dà fún wa. w22.03 17 ¶11-12

Wednesday, August 30

Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún.​—Ẹ́kís. 34:6, 7.

Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí? Bíbélì sọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan la lè nífẹ̀ẹ́, irú bí “iṣẹ́ àgbẹ̀,” “wáìnì àti òróró,” “ẹ̀kọ́,” “ìmọ̀,” “ọgbọ́n” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (2 Kíró. 26:10; Òwe 12:1; 21:17; 29:3) Àmọ́ ṣá o, a kì í ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sáwọn nǹkan yìí, àwa èèyàn nìkan ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo èèyàn ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ yìí hàn sí àfi àwọn tó bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Torí náà, Ọlọ́run máa ń jẹ́ olóòótọ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn ohun rere kan wà tó fẹ́ ṣe fún wọn, ìgbà gbogbo lá sì máa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn. Gbogbo aráyé ni Jèhófà ti fi ìfẹ́ hàn sí. Jésù sọ fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nikodémù pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ [aráyé] gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”​—Jòh. 3:1, 16; Mát. 5:44, 45. w21.11 2 ¶3; 3 ¶6-7

Thursday, August 31

Tí ẹ bá ní ìfaradà, ẹ máa lè pa ẹ̀mí yín mọ́.​—Lúùkù 21:19.

Nǹkan nira gan-an lákòókò tá a wà yìí, ó sì ṣeé ṣe kí nǹkan tún nira jù báyìí lọ lọ́jọ́ iwájú. (Mát. 24:21) Gbogbo wa là ń retí ìgbà tí àwọn ìṣòro yìí á kásẹ̀ nílẹ̀ tí gbogbo ohun tó ń kó ìdààmú bá wa á sì di ohun ìgbàgbé! (Àìsá. 65:16, 17) Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká túbọ̀ lẹ́mìí ìfaradà. Kí nìdí? Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá ní ìfaradà, ẹ máa lè pa ẹ̀mí yín mọ́.” (Lúùkù 21:19) Tá a bá ń ronú nípa àwọn tó nírú ìṣòro táwa náà ní, tí wọ́n sì ń fara dà á láìbọ́hùn, á rọrùn fáwa náà láti fara da àwọn ìṣòro wa. Ta ni àpẹẹrẹ tó dáa jù tó bá dọ̀rọ̀ ìfaradà? Jèhófà ni. Ìdáhùn yẹn lè yà ẹ́ lẹ́nu. Àmọ́ tó o bá rò ó dáadáa, wàá lóye ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Èṣù ló ń ṣàkóso ayé, torí náà kò síbi tá a yíjú sí tí ìṣòro ò sí. Jèhófà lágbára láti fòpin sí gbogbo ìṣòro yẹn lójú ẹsẹ̀, àmọ́ ó ń mú sùúrù di àsìkò tó ti ṣètò láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Róòmù 9:22) Kó tó dìgbà yẹn, Jèhófà ń fara dà á títí àkókò tó ní lọ́kàn á fi pé. w21.07 8 ¶2-4

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́