September
Friday, September 1
Wọ́n ní kó fi àmì kan han àwọn láti ọ̀run.—Mát. 16:1.
Àwọn kan nígbà ayé Jésù gbà pé ó mọ̀ọ̀yàn kọ́ gan-an. Àmọ́ ìyẹn nìkan ò tẹ́ wọn lọ́rùn. Nígbà tó kọ̀ láti fi àmì tí wọ́n béèrè hàn wọ́n, ṣe ni wọ́n kọsẹ̀. (Mát. 16:4) Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ? Wòlíì Àìsáyà sọ nípa Mèsáyà pé: “Kò ní ké jáde tàbí kó gbé ohùn rẹ̀ sókè, kò sì ní jẹ́ ká gbọ́ ohùn rẹ̀ lójú ọ̀nà.” (Àìsá. 42:1, 2) Jésù ò pe àfiyèsí sí ara ẹ̀ nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣe àṣehàn. Jésù ò bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì tàbí kó wọ àwọn aṣọ oyè torí káwọn èèyàn lè gba tiẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbà káwọn èèyàn fi orúkọ oyè pe òun. Nígbà tí Jésù ń jẹ́jọ́ níwájú Ọba Hẹ́rọ́dù, kò ṣe iṣẹ́ àmì kó lè rí ojúure ọba náà. (Lúùkù 23:8-11) Òótọ́ ni pé Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, àmọ́ iṣẹ́ ìwàásù ló kà sí pàtàkì jù. Ó tiẹ̀ sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Torí ìdí tí mo ṣe wá nìyí.”—Máàkù 1:38. w21.05 4 ¶9-10
Saturday, September 2
Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.—Jòh. 17:3.
“Àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” là ń wá. (Ìṣe 13:48) Ká tó lè sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn, a gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ (1) láti lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́, (2) kí wọ́n gba ohun tí wọ́n ń kọ́ gbọ́, (3) kí wọ́n sì máa fi í sílò. (Kól. 2:6, 7; 1 Tẹs. 2:13) Gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ la lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fìfẹ́ hàn sí wọn, tá a sì ń jẹ́ kí ara tù wọ́n nígbà tí wọ́n bá wá sípàdé. (Jòh. 13:35) Ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa lo ọ̀pọ̀ àkókò, á sì sapá gan-an láti ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ kó lè borí “àwọn nǹkan tó ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,” ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ èké àti àwọn ìwà tí ò dáa tó ti mọ́ ọn lára. (2 Kọ́r. 10:4, 5) Ó lè gba ọ̀pọ̀ oṣù ká tó lè ran ẹni náà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kó sì ṣèrìbọmi, àmọ́ ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. w21.07 3 ¶6
Sunday, September 3
Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di èyí tó dára mú ṣinṣin.—1 Tẹs. 5:21.
Ṣé ó dá àwa lójú hán-ún pé òótọ́ lohun tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn àti pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ọ̀nà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń jọ́sìn lónìí? Ó dá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lójú hán-ún pé òtítọ́ ni òun gbà. (1 Tẹs. 1:5) Kì í ṣe bọ́rọ̀ ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù ló mú kó gbà bẹ́ẹ̀. Ohun tó mú kó gbà bẹ́ẹ̀ ni pé ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Ó gbà pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tím. 3:16) Àwọn nǹkan wo ni Pọ́ọ̀lù rí nínú Ìwé Mímọ́? Ó rí ẹ̀rí tó dájú pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ò gba ẹ̀rí yẹn rárá. Àwọn alágàbàgebè yẹn sọ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run làwọn fi ń kọ́ àwọn èèyàn, àmọ́ ohun tínú Ọlọ́run ò dùn sí ni wọ́n ń ṣe. (Títù 1:16) Pọ́ọ̀lù ò ṣe bíi tiwọn. Kò gba èyí tó wù ú nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́, kó wá fi èyí tó kù sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, “gbogbo ìpinnu Ọlọ́run” ló fi ń kọ́ àwọn èèyàn.—Ìṣe 20:27. w21.10 18 ¶1-2
Monday, September 4
Kò sí èèyàn tó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba tó rán mi fà á.—Jòh. 6:44.
Bá a ṣe ń gbìn tá a sì ń bomi rin, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé Ọlọ́run ló ń mú kó dàgbà. (1 Kọ́r. 3:6, 7) Gbogbo èèyàn ló ṣeyebíye lójú Jèhófà. Abájọ tó fi fún wa láǹfààní láti máa bá Ọmọ rẹ̀ ṣiṣẹ́ bó ṣe ń kó àwọn èèyàn jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé. (Hág. 2:7) Ṣe ni iṣẹ́ ìwàásù wa dà bí iṣẹ́ àwọn tó ń gbẹ̀mí là. A dà bí àwùjọ àwọn tó ń gbẹ̀mí là tí wọ́n rán láti dóòlà ẹ̀mí àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi tó ń rì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba lára wọn ni wọ́n á lè dóòlà ẹ̀mí ẹ̀, iṣẹ́ gbogbo àwọn tó ń gbẹ̀mí là náà ò já sásán. Bákan náà lọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù wa rí. A ò mọ bí àwọn tá a ṣì máa rí yọ nínú ayé Èṣù yìí ṣe máa pọ̀ tó. Ẹnikẹ́ni lára wa ni Jèhófà sì lè lò láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Andreas tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Bòlífíà sọ pé: “Mo gbà pé àjọṣe gbogbo wa ni tẹ́nì kan bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó sì ṣèrìbọmi.” Ká máa rántí pé àwa nìkan kọ́ là ń ṣiṣẹ́ yìí, torí náà ká má jẹ́ kó sú wa. Tá ò bá dẹwọ́, Jèhófà máa bù kún wa, àá sì máa láyọ̀ bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ náà. w21.05 19 ¶19-20
Tuesday, September 5
Kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ìdẹkùn Èṣù.—2 Tím. 2:26.
Ohun tó máa ń jẹ àwọn ọdẹ lọ́kàn ni bí wọ́n ṣe máa rí ẹran mú tàbí kí wọ́n rí ẹran pa. Wọ́n lè lo onírúurú páńpẹ́ láti fi dẹkùn mú ẹran, ìyẹn sì bá ohun tí ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù sọ mu. (Jóòbù 18:8-10) Ọgbọ́n wo ni àwọn ọdẹ máa ń dá kí wọ́n lè tan ẹran sínú páńpẹ́? Wọ́n máa ń kíyè sí ìṣe ẹran tí wọ́n fẹ́ mú. Ibo ló máa ń gbà? Kí ló nífẹ̀ẹ́ sí? Irú páńpẹ́ wo ló lè mú un? Ohun tí Sátánì máa ń ṣe gan-an nìyẹn. Ó máa ń kíyè sí ohun tá à ń ṣe, ibi tá a máa ń lọ àtohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí. Á wá dẹ páńpẹ́ kan tó ronú pé á mú wa láìfura. Síbẹ̀, Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tí ọwọ́ Sátánì bá tiẹ̀ bà wá, a ṣì lè bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní kó sí i lọ́wọ́. Àwọn nǹkan méjì tí Sátánì fi ń rí àwọn èèyàn mú jù ni ìgbéraga àti ojúkòkòrò. Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń lo àwọn páńpẹ́ yìí, ó sì ti rí ọ̀pọ̀ èèyàn mú. Kódà, Bíbélì fi Sátánì wé pẹyẹpẹyẹ tó máa ń tan àwọn tó fẹ́ mú sínú páńpẹ́ rẹ̀. (Sm. 91:3) Àmọ́ kò sídìí tó fi yẹ ká kó sínú páńpẹ́ Sátánì torí pé Jèhófà ti jẹ́ ká mọ àwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n rẹ̀.—2 Kọ́r. 2:11. w21.06 14 ¶1-2
Wednesday, September 6
Ewú orí jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.—Òwe 16:31.
Ẹni iyì làwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́, wọ́n sì ṣeyebíye gan-an. Kódà, Bíbélì fi ewú orí wọn wé adé ẹwà. (Òwe 20:29) Àmọ́, ó rọrùn láti gbójú fò wọ́n. Àwọn ọ̀dọ́ tó bá mọyì àwọn àgbàlagbà máa ń rí àǹfààní tó níye lórí ju owó lọ. Àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́ ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. Ó mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an, ó sì mọyì àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní. Inú Jèhófà máa ń dùn tó bá ń rí i táwọn àgbàlagbà ń sọ fáwọn ọ̀dọ́ nípa àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní àtàwọn ohun tí wọ́n ti kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Jóòbù 12:12; Òwe 1:1-4) Jèhófà tún mọyì ẹ̀mí ìfaradà tí wọ́n ní. (Mál. 3:16) Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà ò yingin láìka ọ̀pọ̀ ìṣòro tí wọ́n kojú nígbèésí ayé wọn sí. Ìrètí tí wọ́n ní ti túbọ̀ dá wọn lójú ju ti ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn torí pé wọ́n ṣì ń kéde orúkọ rẹ̀ “kódà nígbà arúgbó wọn.”—Sm. 92:12-15. w21.09 2 ¶2-3
Thursday, September 7
Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò, nígbà náà, yóò láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe.—Gál. 6:4.
Ó yẹ ká máa yẹ ara wa wò látìgbàdégbà. A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń fi ara mi wé àwọn míì, ṣé mo sì máa ń ronú pé mo dáa jù wọ́n lọ? Ṣé torí káwọn míì lè gbà pé èmi ni mo dáa jù ni mo ṣe ń ṣe gbogbo ohun tí mò ń ṣe nínú ìjọ àbí mò ń ṣe bíi pé mo sàn ju arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan lọ? Àbí torí kí n lè múnú Jèhófà dùn ni mo ṣe ń ṣiṣẹ́ kára?’ Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká má ṣe máa fi ara wa wé àwọn míì. Kí nìdí? Ìdí kan ni pé tá a bá ronú pé a sàn ju arákùnrin kan lọ, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. Ìdí míì ni pé tá a bá ń fi ara wa wé àwọn míì, tá a sì ronú pé wọ́n sàn jù wá lọ, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀wẹ̀sì. (Róòmù 12:3) Ó yẹ ká rántí pé kì í ṣe torí pé a rẹwà, a mọ̀rọ̀ sọ tàbí torí pé àwọn èèyàn mọ̀ wá gan-an ni Jèhófà fi fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó fà wá torí ó mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun, a sì ṣe tán láti tẹ́tí sí Jésù Ọmọ òun.—Jòh. 6:44; 1 Kọ́r. 1:26-31. w21.07 14-15 ¶3-4
Friday, September 8
Ẹ máa di tuntun nínú agbára tó ń darí ìrònú yín.—Éfé. 4:23.
Ká tó lè yí èrò inú wa pa dà, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà. Rí i pé ò ń ṣe àwọn nǹkan yìí déédéé, kó o sì bẹ Jèhófà kó o má bàa dẹwọ́. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó o máa fi ara ẹ wé àwọn míì mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà máa jẹ́ kó o tètè mọ̀ tó o bá ti ń jowú tàbí tó ò ń gbéra ga, á sì jẹ́ kó o tètè ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. (2 Kíró. 6:29, 30) Jèhófà mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Ó mọ bá a ṣe ń sapá tó láti borí ẹ̀mí burúkú tó wà nínú ayé yìí àti àìpé wa. Bí Jèhófà ṣe ń rí bá a ṣe ń sapá láti borí àwọn nǹkan yìí, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tó ní fún wa á túbọ̀ máa jinlẹ̀ sí i. Jèhófà lo àpèjúwe ìfẹ́ tó wà láàárín ìyá àti ọmọ ká lè lóye bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. (Àìsá. 49:15) Inú wa mà dùn o láti mọ̀ pé irú ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwa náà nìyẹn bó ṣe ń rí i tá à ń sapá láti ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀! w21.07 24-25 ¶17-19
Saturday, September 9
Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń yọ̀.—Róòmù 12:15.
A lè láyọ̀ tá a bá sa gbogbo ipá wa lẹ́nu iṣẹ́ tá à ń ṣe báyìí nínú ìjọsìn Jèhófà. Jẹ́ kí ‘ọwọ́ rẹ dí gan-an’ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kó o sì máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ìjọ. (Ìṣe 18:5; Héb. 10:24, 25) Rí i pé ò ń múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, kó o lè dáhùn lọ́nà tó máa gbé àwọn ará ró. Fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí wọ́n bá fún ẹ nípàdé àárín ọ̀sẹ̀. Tí wọ́n bá gbé iṣẹ́ èyíkéyìí fún ẹ nínú ìjọ, rí i pé o tètè ṣe é, kó o sì jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Má fojú kéré ohunkóhun tí wọ́n bá fún ẹ nínú ìjọ. Ṣe ni kó o máa sapá láti sunwọ̀n sí i. (Òwe 22:29) Bó o bá ṣe ń sapá tó, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú, ayọ̀ ẹ á sì máa pọ̀ sí i. (Gál. 6:4) Yàtọ̀ síyẹn, táwọn míì bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù ẹ́, á rọrùn fún ẹ láti bá wọn yọ̀.—Gál. 5:26. w21.08 22 ¶11
Sunday, September 10
Ọgbọ́n tó wá láti òkè á kọ́kọ́ jẹ́ mímọ́, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó ṣe tán láti ṣègbọràn, ó máa ń ṣàánú gan-an, ó sì ń so èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, kì í sì í ṣe àgàbàgebè.— Jém. 3:17.
Tá a bá fẹ́ jẹ́ kí Jèhófà kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, kò yẹ ká máa gbéra ga. Bí àrùn ṣe máa ń ṣèpalára fún ọkàn tí kì í jẹ́ kó ṣiṣẹ́ dáadáa, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbéraga kì í jẹ́ ká ṣègbọràn sí Jèhófà. Àwọn Farisí jẹ́ kí ọkàn wọn le débi pé wọn ò gba ẹ̀rí tó dájú tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn wọ́n pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run. (Jòh. 12:37-40) Ohun tí wọ́n ṣe yẹn léwu gan-an torí kò ní jẹ́ kí wọ́n níyè àìnípẹ̀kun. (Mát. 23:13, 33) Ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa tọ́ wa sọ́nà nínú ìwà wa àti èrò wa, kí wọ́n sì jẹ́ ká máa ṣe ìpinnu tó dáa. Nítorí pé Jémíìsì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó jẹ́ kí Jèhófà kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó ní ló sì mú kó di olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa. w22.01 10 ¶7
Monday, September 11
Ẹ máa béèrè.—Mát. 7:7.
Tá a bá ń “tẹra mọ́ àdúrà gbígbà,” ó dájú pé Baba wa ọ̀run máa gbọ́ wa. (Kól. 4:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máa ṣe wá bíi pé Jèhófà ò tètè dá wa lóhùn, síbẹ̀ Jèhófà ṣèlérí pé òun máa dáhùn àdúrà wa “ní àkókò tó tọ́.” (Héb. 4:16) Torí náà, kò yẹ ká máa dá Jèhófà lẹ́bi tí ohun tá à ń béèrè ò bá ṣẹlẹ̀ lásìkò tá a fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún làwọn kan ti ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run fòpin sí ayé burúkú yìí. Kódà, Jésù náà sọ pé ká máa gbàdúrà kí Ìjọba Ọlọ́run dé. (Mát. 6:10) Àmọ́ ìwà agọ̀ gbáà ló máa jẹ́ tẹ́nì kan bá fi Jèhófà sílẹ̀ torí òpin ò dé lásìkò táwa èèyàn retí! (Háb. 2:3; Mát. 24:44) Ohun tó máa bọ́gbọ́n mu ni pé ká dúró de Jèhófà ká sì nígbàgbọ́ pé ó máa dáhùn àdúrà wa. Jèhófà ti yan “ọjọ́ àti wákàtí” tí òpin máa dé. Torí náà, àsìkò tó tọ́ lòpin máa dé, àsìkò yẹn ló sì máa ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní jù.—Mát. 24:36; 2 Pét. 3:15. w21.08 10 ¶10-11
Tuesday, September 12
Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.—Fílí. 2:3.
Àwọn àgbàlagbà tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ mọ̀ pé àwọn ò lè ṣe tó báwọn ṣe máa ń ṣe nígbà táwọn wà lọ́dọ̀ọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn alábòójútó àyíká. Tí wọ́n bá ti pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, wọ́n máa fiṣẹ́ alábòójútó àyíká sílẹ̀, wọ́n á sì máa bójú tó iṣẹ́ míì. Ká sòótọ́, ìyẹn kì í rọrùn rárá. Ìdí ni pé ó wù wọ́n láti máa lo ara wọn fáwọn ará. Àmọ́ wọ́n mọ̀ pé àwọn ọ̀dọ́ tó lókun máa lè ṣiṣẹ́ náà dáadáa. Ṣe ni wọ́n fìwà jọ àwọn ọmọ Léfì ní Ísírẹ́lì àtijọ́ tí wọ́n máa ń fiṣẹ́ ìsìn wọn ní àgọ́ ìjọsìn sílẹ̀ tí wọ́n bá ti pé ẹni àádọ́ta (50) ọdún. Kì í ṣe iṣẹ́ ìsìn kan pàtó ló ń fún àwọn ọmọ Léfì yìí láyọ̀. Àmọ́ wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá yàn fún wọn, wọ́n sì máa ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́. (Nọ́ń. 8:25, 26) Bákan náà lónìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alábòójútó àyíká yìí kì í bẹ àwọn ìjọ wò mọ́, ìbùkún ńlá ni wọ́n jẹ́ fáwọn ìjọ tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́. w21.09 8-9 ¶3-4
Wednesday, September 13
Bàbá, mo ti ṣẹ̀ sí ọ̀run, mo sì ti ṣẹ̀ ọ́. Mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè pè ní ọmọ rẹ mọ́.—Lúùkù 15:21.
Nínú Lúùkù 15:11-32, Jésù sọ ìtàn nípa ọmọ onínàákúnàá. Ọ̀dọ́kùnrin náà ṣọ̀tẹ̀ sí bàbá ẹ̀, ó kúrò nílé, ó sì rìnrìn àjò “lọ sí ilẹ̀ tó jìnnà gan-an.” Nígbà tó débẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í náwó ẹ̀ nínàákúnàá, ó sì ń gbé ìgbé ayé oníwà pálapàla. Nígbà tí ọwọ́ ìyà bà á, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ìpinnu tí ò dáa tóun ṣe. Ó wá rí i pé ìgbésí ayé òun nítumọ̀ nígbà tóun wà lọ́dọ̀ Bàbá òun. Jésù sọ pé “nígbà tí orí rẹ̀ wálé,” ó pinnu láti pa dà sílé kó lè bẹ bàbá rẹ̀ pé kó dárí ji òun. Ó dáa gan-an bí ọ̀dọ́kùnrin náà ṣe kábàámọ̀ ohun tó ṣe. Àmọ́, ó tún gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan míì! Ọmọ onínàákúnàá yẹn ṣe ohun tó fi hàn pé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Ẹ̀kọ́ pàtàkì làwọn alàgbà lè rí kọ́ látinú àkàwé tí Jésù ṣe yìí. Ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n bá fẹ́ mọ̀ bóyá ẹnì kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn. w21.10 5 ¶14-15
Thursday, September 14
Màá mi ọ̀run àti ayé jìgìjìgì.—Hág. 2:6.
Kí la ò ní mì tàbí mú kúrò? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí a ṣe rí i pé a máa tẹ́wọ́ gba Ìjọba kan tí kò ṣeé mì, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa . . . ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ọ̀wọ̀.” (Héb. 12:28) Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló máa ṣẹ́ kù, òun nìkan ṣoṣo ló sì máa dúró títí láé! (Sm. 110:5, 6; Dán. 2:44) Àkókò ń lọ, a ò sì rọ́jọ́ mú so lókùn! Torí náà àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ pinnu. Tí wọ́n bá pinnu pé ayé yìí làwọn máa tì lẹ́yìn, wọ́n máa pa run títí láé. Àmọ́ tí wọ́n bá pinnu pé Jèhófà làwọn máa sìn tí wọ́n sì ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, wọ́n máa wà láàyè títí láé. (Héb. 12:25) Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ló máa jẹ́ káwọn èèyàn lè ṣe ìpinnu pàtàkì yìí. Ẹ sì jẹ́ ká máa fi ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa wa sọ́kàn pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.”—Mát. 24:14. w21.09 19 ¶18-20
Friday, September 15
Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.—Héb. 13:5.
Ẹ̀yin alàgbà, ẹ máa tu àwọn tí wọ́n yọ èèyàn wọn lẹ́gbẹ́ nínú torí ojúṣe pàtàkì tí Jèhófà ti gbé fún yín ni. (1 Tẹs. 5:14) Lára ohun tẹ́ ẹ lè ṣe ni pé, kẹ́ ẹ máa bá wọn sọ̀rọ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé. Bákan náà, ẹ máa bẹ̀ wọ́n wò, kẹ́ ẹ sì gbàdúrà fún wọn. Ẹ tún lè bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí kẹ́ ẹ pè wọ́n wá sí ìjọsìn ìdílé yín. Ó ṣe pàtàkì káwọn alàgbà máa bójú tó àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn, kí wọ́n sì máa fi àánú àti ìfẹ́ hàn sí wọn. (1 Tẹs. 2:7, 8) Bíbélì sọ pé Jèhófà “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9) Bí ẹnì kan bá tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ẹ̀mí ẹ̀ ṣì ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Rántí pé nǹkan ńlá ló ná Jèhófà láti ra ẹnì kọ̀ọ̀kan wa pa dà, ìyẹn sì ni ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Jèhófà máa ń fìfẹ́ ran àwọn tó ti ṣáko lọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ ẹ̀. Ó wù ú gan-an pé kí wọ́n pa dà bá a ṣe rí i nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ọmọ onínàákúnàá.—Lúùkù 15:11-32. w21.09 30-31 ¶17-19
Saturday, September 16
Ẹ sì ti wọlé láti jàǹfààní iṣẹ́ wọn.—Jòh. 4:38.
Tó ò bá lè wàásù bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ nítorí àìsàn ńkọ́? O ṣì lè máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọba Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀ lọ gba ìdílé wọn àtàwọn ẹrù wọn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ámálékì. Ó ti rẹ ọgọ́rùn-ún méjì (200) lára àwọn ọkùnrin náà débi pé wọn ò lè jà mọ́, torí náà àwọn ni wọ́n dúró ti ẹrù. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣẹ́gun, Dáfídì pàṣẹ pé kí wọ́n pín ẹrù tí wọ́n kó bọ̀ látojú ogun lọ́gbọọgba. (1 Sám. 30:21-25) Bí iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn tá à ń ṣe kárí ayé ṣe rí náà nìyẹn. Lóòótọ́, o lè má lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́ tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ gbé, inú ẹ á máa dùn ní gbogbo ìgbà tí ẹnì kan bá ṣèrìbọmi. Jèhófà ń kíyè sí gbogbo ohun tá à ń ṣe, ó sì ń bù kún wa. Ó tún ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè láyọ̀ bá a ṣe ń ṣe ipa tiwa lẹ́nu iṣẹ́ ìkórè yìí. (Jòh. 14:12) Torí náà, ó dájú pé tá ò bá jáwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé, inú Jèhófà máa dùn sí wa! w21.10 28 ¶15-17
Sunday, September 17
Ògo àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn.—Òwe 20:29.
Bára ṣe ń dara àgbà, ó lè máa ṣe wá bíi pé a ò ní wúlò fún Jèhófà bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má ní okun bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, a lè pinnu láti fi ọgbọ́n àti ìrírí tá a ní ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú, kí wọ́n sì túbọ̀ wúlò nínú ètò Ọlọ́run. Ó ṣe pàtàkì káwọn àgbàlagbà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kí wọ́n tó lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́. Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń gbà pé àwọn míì sàn ju òun lọ. (Fílí. 2:3, 4) Àwọn àgbàlagbà tó bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń gbà pé onírúurú ọ̀nà lèèyàn lè gbà bójú tó iṣẹ́ kan. Torí náà, wọn kì í rin kinkin mọ́ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe nǹkan tẹ́lẹ̀. (Oníw. 7:10) Òótọ́ ni pé àwọn àgbàlagbà ní ọ̀pọ̀ ìrírí tí wọ́n lè fi ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́. Síbẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé “ìrísí ayé yìí ń yí pa dà,” ó sì ṣe pàtàkì pé káwọn náà ṣe àwọn àtúnṣe kan bí nǹkan ṣe ń yí pa dà.—1 Kọ́r. 7:31. w21.09 8 ¶1, 3
Monday, September 18
Jèhófà, ta ló dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run? Ta ló dà bí rẹ, ìwọ tí o fi hàn pé ẹni mímọ́ jù lọ ni ọ́?—Ẹ́kís. 15:11.
Jèhófà kò ní sọ pé káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa hùwà àìmọ́ torí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà. Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa rántí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, wọ́n kọ àkọlé kan sára wúrà pẹlẹbẹ tó wà lára láwàní àlùfáà àgbà. Àkọlé náà sọ pé: “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà.” (Ẹ́kís. 28:36-38) Ọ̀rọ̀ tó wà lára wúrà pẹlẹbẹ yẹn ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé lóòótọ́ ni Jèhófà jẹ́ mímọ́. Àmọ́ tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọmọ Ísírẹ́lì kan ò lè rí àkọlé náà ńkọ́ torí pé kò lè dé ibi tí àlùfáà àgbà wà? Ṣé ẹni náà á ṣì mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ mímọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́kùnrin, lóbìnrin àti lọ́mọdé ló gbọ́ nígbà tí wọ́n ń ka Òfin yẹn. (Diu. 31:9-12) Tó o bá wà níbẹ̀, ìwọ náà máa gbọ́ gbólóhùn yìí: “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, . . . ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, torí èmi jẹ́ mímọ́.” “Kí ẹ jẹ́ mímọ́ fún mi, torí èmi Jèhófà jẹ́ mímọ́.”—Léf. 11:44, 45; 20:7, 26. w21.12 3 ¶6-7
Tuesday, September 19
Ẹ má jẹ́ kí àníyàn kó yín lọ́kàn sókè mọ́.—Lúùkù 12:29.
Àwọn kan lè máa ṣàníyàn nípa ohun ìní tara. Wọ́n lè máa gbé lórílẹ̀-èdè tí ọrọ̀ ajé wọn ti dẹnu kọlẹ̀, tí ò sì rọrùn láti ríṣẹ́. Ó lè ṣòro fún wọn láti rí owó tí wọ́n á máa fi gbọ́ bùkátà ìdílé wọn. Tàbí kó jẹ́ pé ẹni tó lè máa gbọ́ bùkátà ìdílé wọn ti kú, tí ò sì sẹ́ni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ́. Tá ò bá ṣàníyàn nípa àwọn ìṣòro wa, àmọ́ tá a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa ṣe wá láǹfààní. Ẹ rántí pé Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa bójú tó wa tá a bá fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. (Mát. 6:32, 33) Àwọn ẹ̀rí wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé ó máa ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀. (Diu. 8:4, 15, 16; Sm. 37:25) Tí Jèhófà bá lè máa pèsè fáwọn ẹyẹ àtàwọn ewéko tó ń yọ òdòdó, ó dájú pé ó máa pèsè fáwa náà. Torí náà, kò yẹ ká máa ṣàníyàn nípa ohun tá a máa jẹ tàbí ohun tá a máa wọ̀! (Mát. 6:26-30; Fílí. 4:6, 7) Ìfẹ́ táwọn òbí ní sáwọn ọmọ wọn ló ń jẹ́ kí wọ́n pèsè nǹkan tara fún wọn. Bákan náà, ìfẹ́ tí Bàbá wa ọ̀run ní sáwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ló ń jẹ́ kó pèsè àwọn nǹkan tara fún wa. w21.12 17 ¶4-5; 18 ¶8
Wednesday, September 20
Jèhófà ò fi Jósẹ́fù sílẹ̀, ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí i.—Jẹ́n. 39:21.
Ṣé ẹnì kan nínú ìjọ ti ṣẹ̀ ẹ́ rí tọ́rọ̀ náà sì dùn ẹ́ gan-an? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jósẹ́fù táwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ hùwà àìdáa sí. Bó ṣe máa múnú Jèhófà dùn ló gbájú mọ́. Jèhófà náà sì san án lẹ́san torí pé ó mú sùúrù, ó sì fara dà á. Nígbà tó yá, Jósẹ́fù dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ ẹ́, ìyẹn sì mú kó rí ọwọ́ Jèhófà nígbèésí ayé ẹ̀. (Jẹ́n. 45:5) Bíi ti Jósẹ́fù, tá a bá sún mọ́ Jèhófà tá a sì fọ̀rọ̀ náà sọ́wọ́ ẹ̀, ara máa tù wá. (Sm. 7:17; 73:28) Tó bá jẹ́ pé ò ń fara da ìwà àìdáa kan tí wọ́n hù sí ẹ tàbí ìṣòro míì tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ, rántí pé Jèhófà wà nítòsí “àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn.” (Sm. 34:18) Inú ẹ̀ ń dùn bó ṣe ń rí i pé ò ń mú sùúrù, o sì gbẹ́kẹ̀ lé òun. (Sm. 55:22) Jèhófà ni Onídàájọ́ gbogbo ayé, kò sì sóhun tó pa mọ́ fún un. (1 Pét. 3:12) Torí náà tó o bá ní àwọn ìṣòro tó ń bá ẹ fínra, tó ò sì lè yanjú báyìí, ṣé wàá dúró de Jèhófà? w21.08 11 ¶14; 12 ¶16
Thursday, September 21
Ẹ máa fi òye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.—Éfé. 5:17.
Ó bọ́gbọ́n mu pé ká fi ìgbésí ayé wa ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn. Torí náà, ó yẹ ká yan ìgbésí ayé tó dáa jù lọ. Tá a bá fẹ́ lo àkókò wa lọ́nà tó dáa, ó máa ń gba pé ká wo àwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe, ká sì yan èyí tó yẹ ká fi sípò àkọ́kọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tí Jésù lọ kí Màríà àti Màtá nílé wọn. Torí pé inú Màtá dùn láti gba Jésù lálejò, ìyẹn ló jẹ́ kó fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti se àsè ńlá fún un. Àmọ́ Màríà ní tiẹ̀ jókòó sọ́dọ̀ Jésù, ó sì ń gbọ́ ohun tó ń sọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Màtá fẹ́ ṣe ò burú rárá, Jésù sọ pé Màríà ní tiẹ̀ “yan ìpín tó dáa jù.” (Lúùkù 10:38-42, àlàyé ìsàlẹ̀) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Màríà lè gbàgbé oúnjẹ tí wọ́n jẹ lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ ó dájú pé kò lè gbàgbé ohun tó kọ́ lọ́dọ̀ Jésù. Bí Màríà ṣe mọyì àkókò tó lò pẹ̀lú Jésù, bẹ́ẹ̀ làwa náà mọyì àkókò táà ń lò pẹ̀lú Jèhófà. w22.01 27 ¶5-6
Friday, September 22
Ṣé o rí bí Áhábù ṣe rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítorí mi?—1 Ọba 21:29.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Áhábù rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jèhófà, ohun tó ṣe lẹ́yìn náà jẹ́ ká mọ̀ pé kò ronú pìwà dà látọkàn wá. Kò ṣe ohunkóhun láti fòpin sí ìjọsìn Báálì ní ilẹ̀ náà, kò sì gbé ìjọsìn Jèhófà lárugẹ. Lẹ́yìn tí Áhábù kú, Jèhófà sọ ojú tóun fi wo ọkùnrin yẹn. Wòlíì Jéhù sọ nípa Áhábù pé èèyàn “burúkú” ni. (2 Kíró. 19:1, 2) Rò ó wò ná: Ká sọ pé Áhábù ronú pìwà dà látọkàn wá ni, ó dájú pé wòlíì yẹn ò ní pè é ní èèyàn burúkú tó kórìíra Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Áhábù kábàámọ̀ ohun tó ṣe déwọ̀n àyè kan, ó ṣe kedere pé kò ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Áhábù ṣe? Nígbà tí Èlíjà sọ fún Áhábù pé Jèhófà máa fìyà jẹ òun àti ìdílé rẹ̀, Áhábù kọ́kọ́ rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìyẹn sì dáa. Àmọ́, àwọn ohun tó ṣe lẹ́yìn náà fi hàn pé kò ronú pìwà dà látọkàn wá. Èyí jẹ́ ká rí i pé ìrònúpìwàdà tó tọkàn wá kọjá kéèyàn kàn sọ pé òun kábàámọ̀ ohun tóun ṣe. w21.10 3 ¶4-5, 7-8
Saturday, September 23
A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí.—Mát. 24:14.
Wòlíì ni Àìsáyà, ó sì ṣeé ṣe kí ìyàwó ẹ̀ náà máa sọ tẹ́lẹ̀, torí Bíbélì sọ pé “wòlíì obìnrin” ni. (Àìsá. 8:1-4) Ó dájú pé Àìsáyà àti ìyàwó ẹ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Jèhófà nínú ìdílé wọn. Lónìí, táwọn tọkọtaya bá ń fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ìyẹn máa fi hàn pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni wọ́n fẹ́ fi ìgbésí ayé wọn ṣe. Tí wọ́n bá jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, tí wọ́n sì ń rí bí wọ́n ṣe ń ṣẹ, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Títù 1:2) Wọ́n tún lè ronú nípa bí wọ́n ṣe lè kópa nínú bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ṣe máa ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn náà lè ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ pé a máa wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo ilẹ̀ ayé kí òpin tó dé. Tó bá dá àwọn tọkọtaya lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì máa ṣẹ, wọ́n á túbọ̀ pinnu pé gbogbo ohun tí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bá gbà làwọn máa fún un. w21.11 16 ¶9-10
Sunday, September 24
Ó sọ fún ọmọ ẹ̀yìn náà pé: “Wò ó! Ìyá rẹ!”—Jòh. 19:27.
Ó wu Jésù pé kó tọ́jú ìyá rẹ̀ tó ṣeé ṣe kó ti di opó. Jésù nífẹ̀ẹ́ Màríà gan-an, ó sì fẹ́ rí i dájú pé ó rí àbójútó tó yẹ. Ìdí nìyẹn tó fi fa Màríà lé Jòhánù lọ́wọ́ torí ó mọ̀ pé Jòhánù máa bójú tó o nípa tẹ̀mí. Àtọjọ́ yẹn ni Jòhánù ti mú Màríà sọ́dọ̀, ó sì tọ́jú rẹ̀ bíi pé ìyá ẹ̀ gangan ni. Ẹ ò rí i pé Jésù nífẹ̀ẹ́ ìyá rẹ̀ ọ̀wọ́n, ó sì dájú pé kò gbàgbé bí ìyá rẹ̀ ṣe fìfẹ́ bójú tó o ní kékeré, tó sì tún dúró tì í nígbà tó máa kú! Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ? Nígbà míì, àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn ará máa ń lágbára ju àjọṣe tó wà láàárín àwa àti ìdílé wa lọ. Àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè máa ta kò wá tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa wá tì, àmọ́ Jésù ṣèlérí pé tá ò bá fi Jèhófà àti ètò rẹ̀ sílẹ̀, a máa “gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100)” ohun tá a pàdánù. A máa rí ọ̀pọ̀ àwọn tó máa dà bí ọmọ fún wa, àwọn táá dà bí ẹ̀gbọ́n, àbúrò, ìyá àti bàbá. (Máàkù 10:29, 30) Báwo ló ṣe rí lára ẹ pé o wà nínú ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan torí pé wọ́n nígbàgbọ́, wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn?—Kól. 3:14; 1 Pét. 2:17. w21.04 9-11 ¶7-8
Monday, September 25
Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa pín ohun tí ẹ ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì.—Héb. 13:16.
Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ máa ń jẹ́ ká ṣe kọjá ohun táwọn èèyàn ń retí. Bíi tàwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lóde òní ti pinnu láti máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ̀ wọ́n rí. Bí àpẹẹrẹ, tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn ará máa ń fẹ́ mọ bí wọ́n ṣe máa ṣèrànwọ́. Tí nǹkan ò bá lọ dáadáa fún ẹnì kan nínú ìjọ, kíákíá làwọn ará máa ṣèrànwọ́ fún ẹni náà. Bíi tàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ nílùú Makedóníà, àwọn ará wa náà máa ń ṣe kọjá ohun tá a retí. Wọ́n ń lo àkókò àti okun wọn láti ṣèrànwọ́. Kódà wọ́n ṣe “kọjá agbára wọn” kí wọ́n lè ran àwọn ará tíṣòro dé bá lọ́wọ́. (2 Kọ́r. 8:3) Bákan náà lónìí, àwọn alàgbà tó lákìíyèsí máa ń fi hàn pé àwọn mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nínú ìjọ, wọ́n sì máa ń gbóríyìn fún wọn tí wọ́n bá rí i pé wọ́n fi inúure hàn sáwọn ará. Ọ̀rọ̀ ìṣírí táwọn alàgbà ń fún irú àwọn ará bẹ́ẹ̀ lákòókò tó yẹ ń jẹ́ kí wọ́n máa lókun, kò sì jẹ́ kí nǹkan sú wọn.—Àìsá. 32:1, 2. w21.11 11 ¶14; 12 ¶21
Tuesday, September 26
Fetí sílẹ̀ kí o sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n.—Òwe 22:17.
Gbogbo wa la máa ń nílò ìmọ̀ràn látìgbàdégbà. Nígbà míì, ó lè jẹ́ àwa la máa sọ pé kí ẹnì kan tá a fọkàn tán gbà wá nímọ̀ràn. Ó sì lè jẹ́ arákùnrin kan ló máa sọ fún wa pé a ti fẹ́ “ṣi ẹsẹ̀ gbé” tíyẹn sì máa jẹ́ ká kábàámọ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Gál. 6:1) Yàtọ̀ síyẹn, ó lè jẹ́ pé ẹ̀yìn tá a ṣàṣìṣe lẹnì kan máa bá wa wí. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ tí wọ́n fi gbà wá nímọ̀ràn, ó yẹ ká fetí sí ìmọ̀ràn náà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa ṣe wá láǹfààní, ó sì lè jẹ́ ohun tó máa gba ẹ̀mí wa là nìyẹn! (Òwe 6:23) Ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní gbà wá nímọ̀ràn pé ká máa ‘fetí sílẹ̀, ká sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n.’ Kò sí èèyàn tó mọ gbogbo nǹkan tán, kò sí ká má rí ẹnì kan tó máa ní ìmọ̀ tàbí ìrírí jù wá lọ. (Òwe 12:15) Torí náà, tá a bá ń gba ìmọ̀ràn, ìyẹn á fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, a máa fi hàn pé a mọ̀wọ̀n ara wa, a sì gbà pé àfi káwọn èèyàn ràn wá lọ́wọ́ ká tó lè ṣe àwọn nǹkan kan. Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà [tàbí “olùdámọ̀ràn,” àlàyé ìsàlẹ̀].”—Òwe 15:22. w22.02 8 ¶1-2
Wednesday, September 27
Ẹni tó bá ń bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣàṣeyọrí, àmọ́ ẹni tó bá jẹ́wọ́, tó sì fi wọ́n sílẹ̀ la ó fi àánú hàn sí.—Òwe 28:13.
Kéèyàn ronú pìwà dà tọkàntọkàn kọjá kéèyàn kábàámọ̀ ohun tó ṣe. Ó tún gba pé kẹ́ni náà yí bó ṣe ń ronú pa dà. Bákan náà, ó gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ìwà burúkú náà, kó sì máa ṣèfẹ́ Jèhófà. (Ìsík. 33:14-16) Ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ni bó ṣe máa pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Kí ló yẹ ká ṣe, tá a bá mọ̀ pé ọ̀rẹ́ wa kan ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì? Ṣe la máa dá kún ìṣòro ọ̀rẹ́ wa tá a bá bá a bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀. Ohun kan ni pé kò sí bá a ṣe lè bò ó tí àṣírí ò ní pa dà tú torí pé Jèhófà rí ohun tó ṣẹlẹ̀. (Òwe 5:21, 22) O lè sọ fún ọ̀rẹ́ ẹ pé àwọn alàgbà máa ràn án lọ́wọ́ tó bá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn. Tí ọ̀rẹ́ ẹ bá kọ̀ láti lọ jẹ́wọ́ fáwọn alàgbà, ó yẹ kó o lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn alàgbà. Ìyẹn á sì fi hàn pé o fẹ́ ran ọ̀rẹ́ ẹ lọ́wọ́ lóòótọ́. w21.10 7 ¶19-21
Thursday, September 28
Ẹ [máa] wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.—Fílí. 2:4.
Gbogbo wa la lè máa gbọ́ tàwọn míì ṣáájú tiwa bíi ti Jésù. Bíbélì sọ pé Jésù “gbé ìrísí ẹrú wọ̀.” (Fílí. 2:7) Ohun tó máa ń jẹ́ kí ọ̀gá kan mọyì ẹrú ẹ̀ ni pé ẹrú náà mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́, ó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kínú ọ̀gá ẹ̀ lè dùn sí i. Lọ́nà kan náà, ẹrú Jèhófà ni gbogbo wa, a sì ń ran àwọn ará wa lọ́wọ́, ó dájú pé a máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àtàwọn ará wa. Ó yẹ kó o bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ó máa ń yá mi lára láti lo àkókò àti okun mi kí n lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́? Ṣé mo máa ń tètè yọ̀ǹda ara mi tí wọ́n bá ní ká wá ṣiṣẹ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tàbí ká wá tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe?’ Ká ní o rí i pé ó yẹ kó o ṣàtúnṣe àwọn nǹkan kan nígbèésí ayé ẹ, àmọ́ tí kò rọrùn fún ẹ, kí ló yẹ kó o ṣe? Ṣe ni kó o bẹ Jèhófà taratara nínú àdúrà. Sọ bó ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà, ó máa ‘mú kó wù ẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀, á sì fún ẹ ní agbára láti ṣe é.’—Fílí. 2:13. w22.02 22-23 ¶9-11
Friday, September 29
Màá tù yín lára.—Mát. 11:28.
Onínúure ni Jésù. Kódà nígbà tí nǹkan nira fún un, ó máa ń hùwà pẹ̀lẹ́, ó máa ń fòye báni lò, ìyẹn sì fi hàn pé onínúure ni. (Mát. 11:29, 30) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí obìnrin ará Foníṣíà kan wá bá a pé kó wo ọmọ òun sàn, Jésù ò kọ́kọ́ dá a lóhùn, àmọ́ nígbà tó rí ìgbàgbọ́ tó lágbára tí obìnrin náà ní, ó wo ọmọ ẹ̀ sàn. (Mát. 15:22-28) Jésù fi inúure hàn sí obìnrin náà, àmọ́ ó sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ fún un. Nígbà míì, Jésù máa ń bá àwọn tó fẹ́ràn wí, ìyẹn sì fi hàn pé onínúure ni. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Pétérù fẹ́ dí Jésù lọ́wọ́ kó má bàa ṣe ìfẹ́ Jèhófà, Jésù bá a wí níṣojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù. (Máàkù 8:32, 33) Jésù ò ṣe bẹ́ẹ̀ torí kó lè kó ìtìjú bá Pétérù, àmọ́ ó fẹ́ kí Pétérù mọ̀ pé ohun tó ṣe ò dáa àti pé ó fẹ́ fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù lẹ́kọ̀ọ́ pé kò yẹ kí wọ́n máa kọjá ààyè wọn. Ká sòótọ́, ojú ti Pétérù díẹ̀, àmọ́ ó jàǹfààní látinú ìbáwí tí Jésù fún un. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ la jẹ́ onínúure sáwọn tá a fẹ́ràn, nígbà míì ó yẹ ká bá wọn sòótọ́ ọ̀rọ̀. Tá a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ìlànà inú Bíbélì ló yẹ ká fi gbà wọ́n nímọ̀ràn bíi ti Jésù. w22.03 11 ¶12-13
Saturday, September 30
Ẹ jẹ́ ká máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run . . . nígbà gbogbo, ìyẹn èso ètè wa tó ń kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba.—Héb. 13:15.
Tá a bá ń yin Jèhófà, à ń jọ́sìn ẹ̀ nìyẹn. (Sm. 34:1) Tá a bá ń sọ fáwọn èèyàn nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà àtàwọn iṣẹ́ rere rẹ̀, à ń yìn ín nìyẹn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe fún wa tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Torí náà, tá a bá mọyì gbogbo nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ lójoojúmọ́. Tá a bá ń wàásù, ṣe là ń ‘rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run, ìyẹn èso ètè wa.’ Bá a ṣe máa ń fara balẹ̀ ronú nípa ohun tá a máa sọ ká tó gbàdúrà sí Jèhófà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa fara balẹ̀ ronú nípa ohun tá a máa sọ fáwọn tá a fẹ́ lọ wàásù fún torí “ẹbọ ìyìn” tó dáa jù lọ la fẹ́ rú sí Jèhófà. Torí náà, tá a bá wàásù òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn, ó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn. w22.03 21 ¶8