October
Sunday, October 1
Aláyọ̀ ni ẹni tí kò rí ohunkóhun tó máa mú kó kọsẹ̀ nínú mi.—Mát. 11:6.
Orí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la gbé gbogbo ẹ̀kọ́ wa àti ìgbàgbọ́ wa kà. Láìfi gbogbo nǹkan yìí pè, ọ̀pọ̀ èèyàn ló kọsẹ̀ torí wọ́n gbà pé ọ̀nà ìjọsìn wa ti tutù jù àti pé a kì í ṣe bíi tàwọn míì. Bákan náà, ohun tá à ń wàásù rẹ̀ kò bá wọn lára mu. Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó ń gbé nílùú Róòmù pé: “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́. Ohun tí a gbọ́ sì jẹ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Kristi.” (Róòmù 10:17) Torí náà, ohun tó lè mú kéèyàn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára ni pé kó máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kì í ṣe kó máa lọ́wọ́ nínú àwọn ayẹyẹ tí kò bá Bíbélì mu, bó ti wù kí ayẹyẹ náà gbádùn mọ́ àwọn èèyàn tó. Ó ṣe pàtàkì ká ní ìmọ̀ tó péye ká lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára torí pé “láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa.” (Héb. 11:1, 6) Nípa bẹ́ẹ̀, kò dìgbà tá a bá rí àmì kan láti ọ̀run ká tó gbà pé a ti rí òtítọ́. Tá a bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn nìkan ti tó láti mú kó dá wa lójú pé a ti rí òtítọ́, a ò sì ní ṣiyèméjì. w21.05 4-5 ¶11-12
Monday, October 2
Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti mú kí ìhìn rere tẹ̀ síwájú.—Fílí. 1:12.
Onírúurú ìṣòro ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kojú. Àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n lù ú, tí wọ́n sọ ọ́ lókùúta tí wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. (2 Kọ́r. 11:23-25) Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwọn ìgbà kan wà tóun sapá gan-an láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì. (Róòmù 7:18, 19, 24) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún fara da ohun tó pè ní “ẹ̀gún kan” nínú ara rẹ̀, tó sì bẹ Jèhófà taratara pé kó bá òun mú un kúrò. (2 Kọ́r. 12:7, 8) Jèhófà fún Pọ́ọ̀lù lókun kó lè ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú láìka àwọn ìṣòro tó ní sí. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ohun tí Pọ́ọ̀lù gbé ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó wà látìmọ́lé nílùú Róòmù, ó fìtara wàásù fún àwọn sàràkí-sàràkí lára àwọn Júù, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó tún wàásù fún àwọn aláṣẹ. (Ìṣe 28:17; Fílí. 4:21, 22) Yàtọ̀ síyẹn, ó wàásù fún ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹ̀ṣọ́ Ọba àti gbogbo àwọn tó wá kí i. (Ìṣe 28:30, 31; Fílí. 1:13) Àsìkò yẹn náà ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ mélòó kan, a sì ń jàǹfààní àwọn lẹ́tà yẹn títí dòní. w21.05 21 ¶4-5
Tuesday, October 3
“Má ṣe kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀,” kí ẹ má bàa gbéra ga.—1 Kọ́r. 4:6.
Ìgbéraga mú kí Ọba Ùsáyà kọtí ikún sí ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un, ìyẹn sì mú kó ṣe ohun tí ò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe. Kó tó dìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Ùsáyà gbé ṣe. Bí àpẹẹrẹ, akínkanjú ni lójú ogun, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé, ó sì ní oko rẹpẹtẹ. Kódà, Bíbélì ròyìn pé: “Ọlọ́run tòótọ́ mú kí ó láásìkí.” (2 Kíró. 26:3-7, 10) Bíbélì wá fi kún un pé: “Àmọ́, bó ṣe di alágbára tán, ìgbéraga wọ̀ ọ́ lẹ́wù débi tó fi fa àjálù bá ara rẹ̀.” Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti pàṣẹ pé àwọn àlùfáà nìkan ló lè sun tùràrí nínú tẹ́ńpìlì. Àmọ́ Ọba Ùsáyà kọjá àyè ẹ̀, ó sì lọ sun tùràrí nínú tẹ́ńpìlì. Inú bí Jèhófà sí ohun tó ṣe yìí, ó sì fi ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú. (2 Kíró. 26:16-21) Ṣé ìgbéraga lè wọ̀ wá lẹ́wù, ká sì kọjá àyè wa bíi ti Ùsáyà? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe tá a bá ń ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ. Ká máa rántí pé ẹ̀bùn tàbí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí tá a bá ní, Jèhófà ló fún wa. (1 Kọ́r. 4:7) Torí náà, tá a bá ń gbéra ga, a ò ní wúlò fún Jèhófà. w21.06 16 ¶7-8
Wednesday, October 4
Ẹ má yọ̀ torí pé a mú kí àwọn ẹ̀mí tẹrí ba fún yín, àmọ́ ẹ yọ̀ torí pé a ti kọ orúkọ yín sílẹ̀ ní ọ̀run.—Lúùkù 10:20.
Jésù mọ̀ pé ìgbà gbogbo kọ́ làwọn ọmọ ẹ̀yìn òun á máa ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kódà, a ò mọ iye àwọn tó di onígbàgbọ́ lára àwọn tó kọ́kọ́ gbọ́ ìwàásù àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Torí náà, kì í ṣe àṣeyọrí táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe nìkan ló yẹ kó máa fún wọn láyọ̀. Wọ́n á tún láyọ̀ tí wọ́n bá fi sọ́kàn pé inú Jèhófà ń dùn sí iṣẹ́ àṣekára àwọn. Tá a bá ń fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa, a máa jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni, ńṣe là “ń fúnrúgbìn nítorí ẹ̀mí” torí à ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí wa. Jèhófà sì ti mú kó dá wa lójú pé tá ò bá “jáwọ́” tá ò sì “jẹ́ kó rẹ̀ wá,” a máa jèrè ìyè àìnípẹ̀kun, kódà tá ò bá tiẹ̀ ran ẹnì kankan lọ́wọ́ débi tó fi ṣèrìbọmi.—Gál. 6:7-9. w21.10 26 ¶8-9
Thursday, October 5
Àánú wọn sì ṣe é . . . Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan.—Máàkù 6:34.
Ìgbà kan wà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wàásù gan-an, ó sì ti rẹ̀ wọ́n. Nígbà tí wọ́n máa dé ibi tí wọ́n ti fẹ́ sinmi, wọ́n bá èrò rẹpẹtẹ tó ń dúró dè wọ́n. Torí náà, àánú wọn ṣe Jésù ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní “ọ̀pọ̀ nǹkan.” Jésù fira ẹ̀ sípò àwọn èèyàn yẹn. Ó mọ̀ pé wọ́n ń jìyà, wọ́n nílò ìtùnú, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Bọ́rọ̀ àwọn èèyàn ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Ó lè jọ pé nǹkan ń lọ dáadáa fún wọn, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé wọ́n níṣòro, wọ́n sì nílò ìtùnú. Kódà, ṣe ni wọ́n dà bí àgùntàn tí ò ní olùṣọ́ àgùntàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò mọ Ọlọ́run, wọn ò sì nírètí. (Éfé. 2:12) Tá a bá ronú nípa bí ìgbésí ayé àwọn tí ò mọ Ọlọ́run ṣe rí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ìfẹ́ àti àánú tá a ní sí wọn á mú ká ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀nà tó dáa jù tá a sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. w21.07 5 ¶8
Friday, October 6
Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di agbéraga, . . . kí a má sì máa jowú ara wa.—Gál. 5:26.
Ẹni tó ń gbéra ga máa ń ka ara ẹ̀ sí ju bó ṣe yẹ lọ, tara ẹ̀ nìkan ló sì máa ń mọ̀. Ẹni tó bá ń jowú tàbí tó ń ṣe ìlara máa ń fẹ́ ní ohun táwọn míì ní. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń fẹ́ kí ohun táwọn míì ní bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Ó ṣe kedere pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì ẹ̀, ṣe ló kórìíra ẹ̀. A lè fi ìgbéraga àti owú wé ikán tó ń jẹ igi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé igi náà lè gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, kó sì dùn ún wò lójú, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, tí wọn ò bá ṣe nǹkan kan sí igi náà, ó máa wó lulẹ̀ ni. Lọ́nà kan náà, ẹnì kan lè máa sin Jèhófà kó sì dà bí ẹni tẹ̀mí. Àmọ́ tó bá ń gbéra ga tàbí tó ń jowú, kò ní pẹ́ tó fi máa ṣubú. (Òwe 16:18) Kó tó mọ̀, ó máa fi Jèhófà sílẹ̀ á sì ṣàkóbá fún ara ẹ̀ àtàwọn míì. Ìgbéraga ò ní wọ̀ wá lẹ́wù tá a bá fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wa sílò. Ó ní: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìbínú tàbí ìgbéraga mú yín ṣe ohunkóhun, àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.”—Fílí. 2:3. w21.07 15-16 ¶6-8
Saturday, October 7
Kì í ṣe nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ nìkan ni ìhìn rere tí à ń wàásù fi dé ọ̀dọ̀ yín, ó tún wá nípasẹ̀ agbára, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ àti nípasẹ̀ ìdánilójú tó lágbára.—1 Tẹs. 1:5.
Àwọn kan ronú pé ó yẹ kí ìsìn tòótọ́ lè dáhùn gbogbo ìbéèrè títí kan àwọn ìbéèrè tí Bíbélì ò dáhùn ní tààràtà. Àmọ́ ṣé ìyẹn ṣeé ṣe ṣá? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n “máa wádìí ohun gbogbo dájú,” síbẹ̀ ó gbà pé ọ̀pọ̀ nǹkan lòun ò mọ̀. (1 Tẹs. 5:21) Ó sọ pé “a ní ìmọ̀ dé àyè kan . . . à ń ríran fírífírí nínú dígí onírin.” (1 Kọ́r. 13:9, 12) Kì í ṣe gbogbo nǹkan ni Pọ́ọ̀lù mọ̀, bó sì ṣe rí fáwa náà nìyẹn. Àmọ́, ó mọ àwọn nǹkan pàtàkì tó yẹ kó mọ̀ nípa Jèhófà. Àwọn nǹkan tó mọ̀ yẹn sì jẹ́ kó dá a lójú pé òun ti rí òtítọ́. Ọ̀nà kan tá a lè gbà jẹ́ kí òtítọ́ túbọ̀ dá wa lójú ni pé ká fi ọ̀nà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbà jọ́sìn lónìí wé ọ̀nà tí Jésù sọ pé ká máa gbà jọ́sìn Ọlọ́run. w21.10 18-19 ¶2-4
Sunday, October 8
Tó bá ti lé ní ẹni àádọ́ta (50) ọdún, kó fẹ̀yìn tì.—Nọ́ń. 8:25.
Ẹ̀yin àgbàlagbà, yálà ẹ wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ lè ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Báwo lẹ ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, ẹ ní àfojúsùn kí ẹ sì gbájú mọ́ àwọn nǹkan tágbára yín gbé dípò kẹ́ ẹ máa ronú nípa ohun tẹ́ ò lè ṣe mọ́. Ọba Dáfídì fẹ́ kọ́lé fún Jèhófà, àmọ́ nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ló máa kọ́ ilé náà, Dáfídì ò jiyàn, ó sì fi gbogbo ọkàn ẹ̀ ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn. (1 Kíró. 17:4; 22:5) Dáfídì ò ronú pé òun ló yẹ kóun ṣiṣẹ́ náà torí pé Sólómọ́nì “jẹ́ ọ̀dọ́, kò [sì] ní ìrírí.” (1 Kíró. 29:1) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún gbà pé ìbùkún Jèhófà ló máa jẹ́ kí iṣẹ́ náà yọrí sí rere, kì í ṣe ọjọ́ orí tàbí ìrírí àwọn tó ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ náà. Bíi ti Dáfídì, àwọn àgbàlagbà lónìí máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tí wọ́n ń bójú tó lè yí pa dà, ó sì dá wọn lójú pé Jèhófà máa bù kún àwọn ọ̀dọ́ tó ń ṣe iṣẹ́ táwọn ń ṣe tẹ́lẹ̀. w21.09 9 ¶4; 10 ¶5, 8
Monday, October 9
Yóò darí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, yóò sì kọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ní ọ̀nà rẹ̀.—Sm. 25:9.
Tá a bá ní àfojúsùn nínú ìjọsìn Jèhófà, ọkàn wa á pa pọ̀, ìgbésí ayé wa sì máa nítumọ̀. Àmọ́, ipò wa àtohun tágbára wa gbé ni ká fi pinnu àfojúsùn tá a fẹ́ lé, kì í ṣe ohun táwọn míì ń ṣe. Tó bá jẹ́ pé ohun táwọn míì ń ṣe là ń lé, ìyẹn lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì tọ́wọ́ wa ò bá bà á. (Lúùkù 14:28) Torí pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni ẹ́, o ṣeyebíye lójú ẹ̀, kò sì sí ẹlòmíì tó dà bíi rẹ. Kì í ṣe torí pé o dáa ju àwọn míì lọ ni Jèhófà ṣe fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀. Ó fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀ torí pé ó rí ọkàn ẹ, ó rí i pé o nírẹ̀lẹ̀, o sì ṣe tán láti gbẹ̀kọ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó mọyì bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀. Bó o ṣe ń fara dà á tó o sì jẹ́ olóòótọ́ fi hàn pé o ní “ọkàn tó tọ́, tó sì dáa.” (Lúùkù 8:15) Torí náà, máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa láyọ̀ ‘nítorí ohun tí ìwọ fúnra rẹ ń ṣe.’ —Gál. 6:4. w21.07 24 ¶15; 25 ¶20
Tuesday, October 10
Ẹni tó bá yí ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà kúrò nínú ìṣìnà rẹ̀ máa gbà á lọ́wọ́ ikú.—Jém. 5:20.
Ó máa ń gba pé ká mú sùúrù táwọn èèyàn bá hùwà àìdáa sí wa. Bí àpẹẹrẹ, táwọn alàgbà bá gbọ́ pé ẹnì kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì nínú ìjọ, wọ́n á kọ́kọ́ gbàdúrà fún “ọgbọ́n tó wá láti òkè” kí wọ́n lè mọ bí Jèhófà ṣe fẹ́ kí wọ́n bójú tó ọ̀rọ̀ náà. (Jém. 3:17) Ohun tó jẹ wọ́n lógún ni bí wọ́n ṣe máa “yí ẹlẹ́ṣẹ̀ [náà] pa dà kúrò nínú ìṣìnà rẹ̀” tó bá ṣeé ṣe. (Jém. 5:19, 20) Wọ́n tún máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti dáàbò bo ìjọ, kí wọ́n sì pèsè ìtùnú fún àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kó ẹ̀dùn ọkàn bá. (2 Kọ́r. 1:3, 4) Táwọn alàgbà bá ń bójú tó irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, wọ́n á kọ́kọ́ ṣèwádìí kí wọ́n lè mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn sì lè gba àkókò díẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá gbàdúrà, wọ́n á fi Ìwé Mímọ́ tọ́ ẹni náà sọ́nà, wọ́n á sì fún un ní ìbáwí tí ò “kọjá ààlà.” (Jer. 30:11) Àwọn alàgbà kì í kánjú ṣèpinnu. Tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà lórí àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ìjọ ló máa jàǹfààní. w21.08 11 ¶12-13
Wednesday, October 11
Ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ . . . Àwọn èèyàn rẹ ni yóò jẹ́ èèyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.—Rúùtù 1:16.
Nígbà tí ìyàn kan mú ní Ísírẹ́lì, Náómì, ọkọ ẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn méjèèjì ṣí lọ sí Móábù. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọkọ Náómì kú. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀ méjèèjì fẹ́ ìyàwó. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé nígbà tó yá, àwọn náà kú. (Rúùtù 1:3-5) Àwọn àjálù yìí mú kí Náómì rẹ̀wẹ̀sì gan-an. Kódà, ìbànújẹ́ dorí ẹ̀ kodò débi tó fi sọ pé Jèhófà ti kẹ̀yìn sóun. Nígbà tó ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀, ó sọ nípa Ọlọ́run pé: “Jèhófà ti bínú sí mi.” “Olódùmarè ti mú kí ayé mi korò gan-an.” Ó tún sọ pé: “Jèhófà ló kẹ̀yìn sí mi, Olódùmarè ló sì fa àjálù tó bá mi.” (Rúùtù 1:13, 20, 21) Jèhófà mọ̀ pé “ìnilára lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bíi wèrè.” (Oníw. 7:7) Jèhófà lo Rúùtù láti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Náómì. Rúùtù ran ìyá ọkọ ẹ̀ lọ́wọ́ látọkàn wá, ó sì tù ú nínú kó lè mọ̀ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. w21.11 9 ¶9; 10 ¶10, 13
Thursday, October 12
Máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run.—Jém. 1:5.
Tá a bá ti ń ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò lè ṣe púpọ̀ sí i? Rárá o! Ó yẹ ká ṣì ní àwọn àfojúsùn táá jẹ́ ká lè máa ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa, táá sì jẹ́ ká lè ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́. Ọwọ́ wa máa tẹ àwọn àfojúsùn yìí tá a bá pọkàn pọ̀ sórí bá a ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́ dípò kó jẹ́ pé tara wa nìkan làá máa rò. (Òwe 11:2; Ìṣe 20:35) Àwọn àfojúsùn wo lo lè ní? Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o mọ àwọn àfojúsùn tọ́wọ́ ẹ lè bà. (Òwe 16:3) Bí àpẹẹrẹ, ṣé o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé? Ṣé o lè lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí kó o bá àwọn tó ń kọ́lé ètò Ọlọ́run ṣiṣẹ́? Ṣé o lè kọ́ èdè míì àbí kó o lọ sìn níbi tí àìní wà? w21.08 23 ¶14-15
Friday, October 13
Ìfẹ́ [Jèhófà] tí kì í yẹ̀ wà títí láé.—Sm. 136:1.
Inú Jèhófà máa ń dùn láti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn. (Hós. 6:6) Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì Míkà sọ fún wa pé ká “fẹ́ràn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.” (Míkà 6:8, àlàyé ìsàlẹ̀) Torí náà, ó hàn gbangba pé ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ mọ ohun tí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́. Kí ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? Gbólóhùn náà “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀” fara hàn nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ọgbọ̀n (230) ìgbà. Àmọ́ kí ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? Bí “Àlàyé Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì” yìí ṣe sọ, ó ń tọ́ka sí “ìfẹ́ tí ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tó jẹ́ olóòótọ́, adúróṣinṣin àti adúrótini ní sáwọn èèyàn. Bíbélì sábà máa ń lò ó fún ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sáwa èèyàn, àmọ́ ó tún jẹ́ ìfẹ́ táwa èèyàn ní sí èèyàn bíi tiwa.” Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ tó bá dọ̀rọ̀ ká fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn. Abájọ tí Ọba Dáfídì fi sọ nípa Jèhófà pé: “Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga dé ọ̀run . . . Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ mà ṣeyebíye o, Ọlọ́run!” (Sm. 36:5, 7) Bíi ti Dáfídì, ṣé àwa náà mọyì ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀? w21.11 2 ¶1-2; 3 ¶4
Saturday, October 14
Torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Mát. 6:9.
Ìdílé Jèhófà tóbi gan-an. Lára àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ̀ ni Jésù tó jẹ́ “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá” àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn áńgẹ́lì. (Kól. 1:15; Sm. 103:20) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé àwa èèyàn olóòótọ́ lè pe Jèhófà ní Bàbá wa. Nígbà tí Jésù ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ̀rọ̀, ó pe Jèhófà ní “Baba mi àti Baba yín.” (Jòh. 20:17) Ìgbà tá a bá yara wa sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì ṣèrìbọmi la máa di ara ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé. (Máàkù 10:29, 30) Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, Jésù náà sì gbà bẹ́ẹ̀. Kódà, ojú tó fẹ́ káwa náà fi máa wo Jèhófà nìyẹn. Ó mọ̀ pé Baba tó ṣeé sún mọ́ ni, kì í ṣe apàṣẹwàá. Ohun tó fi bẹ̀rẹ̀ àdúrà náà ni: “Baba wa.” Jésù lè sọ fún wa pé ká máa pe Jèhófà ní “Olódùmarè,” “Ẹlẹ́dàá” tàbí “Ọba ayérayé.” Kò sì sóhun tó burú níbẹ̀ torí àwọn orúkọ oyè yẹn wà nínú Bíbélì. (Jẹ́n. 49:25; Àìsá. 40:28; 1 Tím. 1:17) Kàkà bẹ́ẹ̀, “Baba” ni Jésù ní ká máa pe Jèhófà. w21.09 20 ¶1, 3
Sunday, October 15
Mánásè sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.—2 Kíró. 33:13.
Ọba Mánásè ò gba ìkìlọ̀ tí Jèhófà fún un nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀. Níkẹyìn, “Jèhófà mú kí àwọn olórí ọmọ ogun ọba Ásíríà wá gbéjà [ko Júdà], wọ́n fi ìwọ̀ mú Mánásè, wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é, wọ́n sì mú un lọ sí Bábílónì.” Nígbà tí Mánásè wà lẹ́wọ̀n ní Bábílónì, ó jọ pé ó fara balẹ̀ ronú nípa àwọn nǹkan tó ti ṣe. Ó wá “bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀.” Àmọ́, kò fi mọ síbẹ̀ o. “Ó bẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pé kó ṣíjú àánú wo òun.” Kódà, Mánásè “ń gbàdúrà sí Ọlọ́run.” (2 Kíró. 33:10-12) Nígbà tó yá, Jèhófà dáhùn àdúrà Mánásè. Àwọn àdúrà tí Mánásè gbà jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé ó ti yí pa dà tọkàntọkàn. Torí náà, Jèhófà dárí jì í, ó sì mú kó pa dà di ọba. Mánásè wá ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti fi hàn pé lóòótọ́ lòun ronú pìwà dà. w21.10 4 ¶10-11
Monday, October 16
Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ, nítorí pé wọ́n ní èrè fún iṣẹ́ àṣekára wọn.—Oníw. 4:9.
Pírísílà àti Ákúílà ní láti kúrò ní agbègbè tó ti mọ́ wọn lára, wọ́n á wálé tuntun, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgọ́ pípa tí wọ́n ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ìlú Kọ́ríńtì ni wọ́n kó lọ, nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í péjọ pẹ̀lú ìjọ tó wà níbẹ̀, wọ́n sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti fún àwọn ará tó wà níbẹ̀ lókun. Nígbà tó yá, wọ́n kó lọ sí ìlú míì níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù sí i. (Ìṣe 18:18-21; Róòmù 16:3-5) Ẹ ò rí i pé wọ́n máa láyọ̀ gan-an, wọ́n sì máa gbádùn ìgbésí ayé wọn! Lóde òní, àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó lè fi hàn pé àwọn ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pírísílà àti Ákúílà, tí wọ́n bá fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn. Ìgbà tí àwọn méjì kan bá ń fẹ́ ara wọn sọ́nà ló yẹ kí wọ́n ti jọ sọ ohun tí wọ́n fẹ́ fi ìgbésí ayé wọn ṣe. Táwọn tọkọtaya bá jọ pinnu pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà làwọn máa fayé wọn ṣe, tí wọ́n sì sapá kọ́wọ́ wọn lè tẹ̀ ẹ́, ó dájú pé wọ́n á rí ọwọ́ Jèhófà láyé wọn.—Oníw. 4:12. w21.11 17 ¶11-12
Tuesday, October 17
Kí kálukú yín máa bọ̀wọ̀ fún ìyá rẹ̀ àti bàbá rẹ̀ . . . Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.—Léf. 19:3.
Àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run tó ní ká máa bọlá fáwọn òbí wa. Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé lẹ́yìn tí Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Kí ẹ jẹ́ mímọ́, torí èmi Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́,” ló ṣẹ̀ wá sọ fún wọn ní Léfítíkù 19:3 pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún bàbá àti ìyá wọn. (Léf. 19:2) Tá a bá wo ìmọ̀ràn tí Jèhófà fún wa pé ká máa bọlá fáwọn òbí wa, ó yẹ ká bi ara wa pé ‘Ṣé mò ń bọlá fáwọn òbí mi?’ Tó o bá rí i pé o ò ṣe tó bó ṣe yẹ fáwọn òbí ẹ, sapá kó o lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ti kọjá, àmọ́ ní báyìí, rí i pé ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa wà pẹ̀lú wọn, kó o lè túbọ̀ máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, máa pèsè nǹkan tara tí wọ́n nílò fún wọn. Máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, kó o sì máa tù wọ́n nínú. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yẹn, ṣe lò ń pa àṣẹ tó wà nínú Léfítíkù 19:3 mọ́. w21.12 4-5 ¶10-12
Wednesday, October 18
Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́.—Mát. 7:1.
Ọba Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe àgbèrè pẹ̀lú Bátí-ṣébà, ó sì tún ní kí wọ́n pa ọkọ ẹ̀. (2 Sám. 11:2-4, 14, 15, 24) Ohun tí Dáfídì ṣe yìí fìyà jẹ òun àti ìdílé ẹ̀ títí kan àwọn ìyàwó ẹ̀ tó kù. (2 Sám. 12:10, 11) Ìgbà kan tún wà tí Dáfídì ò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n ka àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, kò sì yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ kí ló wá ṣẹlẹ̀? Àjàkálẹ̀ àrùn pa nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin (70,000) lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì! (2 Sám. 24:1-4, 10-15) Ṣé o máa dá Dáfídì lẹ́jọ́ pé kò yẹ kí Jèhófà dárí jì í? Àmọ́ Jèhófà ò ronú lọ́nà yẹn. Ohun tí Jèhófà wò ni bí Dáfídì ṣe ń fi òótọ́ sin òun bọ̀ látẹ̀yìn wá àti bó ṣe ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni Dáfídì dá, Jèhófà dárí jì í. Jèhófà mọ̀ pé Dáfídì nífẹ̀ẹ́ òun gan-an àti pé ó fẹ́ ṣe ohun tó tọ́. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ibi tá a dáa sí ló máa ń wò.—1 Ọba 9:4; 1 Kíró. 29:10, 17. w21.12 19 ¶11-13
Thursday, October 19
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó pa dà ríran, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e, ó ń yin Ọlọ́run lógo.—Lúùkù 18:43.
Jésù fi àánú hàn sáwọn tó ní àìlera. Ṣé ẹ rántí ìròyìn tí Jésù ní kí wọ́n lọ sọ fún Jòhánù Arinibọmi? Ó ní kí wọ́n sọ fún un pé: “Àwọn afọ́jú ti ń ríran báyìí, àwọn arọ ń rìn, à ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, [a sì] ń jí àwọn òkú dìde.” Nígbà tí wọ́n rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe yìí, “gbogbo èèyàn yin Ọlọ́run.” (Lúùkù 7:20-22) Inú àwa Kristẹni máa ń dùn torí à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó ní ká máa fi àánú hàn sí àwọn tó ní àìlera. Torí náà a máa ń ṣàánú wọn, a máa ń gba tiwọn rò, a sì máa ń mú sùúrù fún wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò fún wa lágbára láti wo àwọn èèyàn sàn lọ́nà ìyanu bíi ti Jésù, a láǹfààní láti máa wàásù ìhìn rere fáwọn afọ́jú àtàwọn tí kò mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. À ń sọ fún wọn nípa Párádísè, níbi tí gbogbo èèyàn ti máa ní ìlera tó dáa, tí wọ́n á sì mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. (Lúùkù 4:18) Kódà ní báyìí, ìhìn rere tá à ń wàásù ẹ̀ ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa yin Ọlọ́run lógo. w21.12 9 ¶5
Friday, October 20
Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ibi tí Jèhófà jẹ́ kó yọrí sí.— Jém. 5:11.
Inú Ìwé Mímọ́ ni Jémíìsì ti máa ń fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ. Ó lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti jẹ́ kí àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ rí i pé tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ bíi ti Jóòbù, Jèhófà máa fún wọn lérè. Jémíìsì fi ẹ̀kọ́ yẹn kọ́ wọn, ó sì lo àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn àti àlàyé tí kò lọ́jú pọ̀. Torí náà, ó fi yé wọn pé Jèhófà ló ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ kì í ṣe òun. Ohun tá a rí kọ́: Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ yéni dáadáa, kó o sì kọ́ni látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, kì í ṣe bí ìmọ̀ wa ṣe tó la fẹ́ fi hàn, àmọ́ a fẹ́ kí wọ́n mọ bí ìmọ̀ Jèhófà ṣe pọ̀ tó àti bó ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wọn. (Róòmù 11:33) Á rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ la fi ń kọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, táwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá fẹ́ ṣèpinnu, a ò ní ṣèpinnu fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì àti ohun tí Jèhófà máa fẹ́ kí wọ́n ṣe. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn, kì í ṣe inú tiwa. w22.01 11 ¶9-10
Saturday, October 21
Kí o sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.—Léf. 19:18.
Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa hùwà ìkà sáwọn èèyàn, àmọ́ àwọn nǹkan míì wà tó fẹ́ ká máa ṣe. Ká nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa bí ara wa jẹ́ nǹkan pàtàkì tí Kristẹni kan gbọ́dọ̀ ṣe, tó bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jésù sọ nípa bí àṣẹ tó wà nínú Léfítíkù 19:18 ti ṣe pàtàkì tó. Ìgbà kan wà tí Farisí kan bi Jésù pé: “Àṣẹ wo ló tóbi jù lọ nínú Òfin?” Jésù sọ fún un pé “àṣẹ tó tóbi jù lọ, tó sì jẹ́ àkọ́kọ́” ni pé ká fi gbogbo ọkàn wa, gbogbo ara wa àti gbogbo èrò wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Lẹ́yìn náà, Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ nínú Léfítíkù 19:18 pé: “Ìkejì tó dà bíi rẹ̀ nìyí: ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ” (Mát. 22:35-40) Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà fìfẹ́ hàn sí ọmọnìkejì wa. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú Léfítíkù 19:18. Ó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san tàbí kí o di ọmọ àwọn èèyàn rẹ sínú.” w21.12 10-11 ¶11-13
Sunday, October 22
Nígbà tó wo ìjì tó ń jà, ẹ̀rù bà á. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í rì, ó ké jáde pé: “Olúwa, gbà mí là!”—Mát. 14:30.
Jésù na ọwọ́ rẹ̀ láti fa àpọ́sítélì Pétérù jáde. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Pétérù lè rìn lórí omi torí pé Jésù ló ń wò. Àmọ́ nígbà tí Pétérù wo ìjì náà, ẹ̀rù bà á, ó sì ṣiyèméjì. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rì nìyẹn. (Mát. 14:24-31) A lè rí nǹkan kọ́ nínú àpẹẹrẹ Pétérù. Nígbà tí Pétérù jáde kúrò nínú ọkọ̀ tó sì bọ́ sórí omi, kò mọ̀ pé ẹ̀rù máa ba òun débi pé òun máa bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó wù ú kó máa rìn lórí omi títí tá á fi dé ọ̀dọ̀ Ọ̀gá rẹ̀. Àmọ́ dípò kó máa wo Jésù, ó jẹ́ kí ìjì yẹn dẹ́rù ba òun. Òótọ́ ni pé àwa ò lè rìn lórí omi lónìí, àmọ́ a máa ń kojú àwọn ìṣòro kan tó máa ń dán ìgbàgbọ́ wa wò. Tá ò bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà mọ́ pé ó máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ìgbàgbọ́ wa ò ní lágbára mọ́. Ìṣòro yòówù ká dojú kọ nígbèésí ayé wa tó dà bí ìjì, Jèhófà ló yẹ ká máa wò, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e pé á ràn wá lọ́wọ́. w21.12 17-18 ¶6-7
Monday, October 23
Màá wá sínú ilé rẹ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tó lágbára.—Sm. 5:7.
Apá kan ìjọsìn wa ni àdúrà, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àṣàrò. Tá a bá ń gbàdúrà, Bàbá wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa là ń bá sọ̀rọ̀ yẹn. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe là ń gba “ìmọ̀ Ọlọ́run” tó jẹ́ Orísun ọgbọ́n. (Òwe 2:1-5) Àṣàrò máa ń jẹ́ ká ronú lórí ohun tá a kọ́ nípa Jèhófà, irú bí àwọn ànímọ́ rẹ̀ àtàwọn nǹkan àgbàyanu tó fẹ́ ṣe fún aráyé. Ọ̀nà tó dáa jù lọ nìyẹn tá a lè gbà lo àkókò wa. Àmọ́ báwo la ṣe lè ṣe é bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wa máa ń dí? Tó bá ṣeé ṣe, wá ibi tó pa rọ́rọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jésù. Kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ó lo ogójì (40) ọjọ́ ní aginjù. (Lúùkù 4:1, 2) Nítorí pé ibi tó pa rọ́rọ́ ni Jésù wà ní aginjù, ìyẹn ló jẹ́ kó lè gbàdúrà sí Jèhófà, kó sì ṣàṣàrò lórí ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ kó ṣe. Ohun tí Jésù ṣe yẹn ló ràn án lọ́wọ́ láti kojú àdánwò tó dé bá a lẹ́yìn náà. w22.01 27-28 ¶7-8
Tuesday, October 24
Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ olùdámọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.—Òwe 15:22, àlàyé ìsàlẹ̀.
Alàgbà tàbí arákùnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ lè pe àfiyèsí wa sí ohun kan tó yẹ ká ṣàtúnṣe lé lórí. Tẹ́nì kan bá fi Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn, ìyẹn fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì yẹ ká gba ìmọ̀ràn náà. Ká sòótọ́, tí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn tó ṣe tààràtà, kì í rọrùn fún wa láti gbà á. Kódà, ó lè bí wa nínú. Kí nìdí? Ó máa ń rọrùn fún wa láti gbà pé aláìpé ni wá, àmọ́ kì í rọrùn láti gbà tẹ́nì kan bá sọ ibi tá a kù sí fún wa. (Oníw. 7:9) A lè má fẹ́ gbà pé òótọ́ lohun tẹ́ni náà sọ. A lè máa ronú pé kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ká bínú torí bó ṣe bá wa sọ̀rọ̀. Kódà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí ẹni náà, ká wá máa sọ pé: ‘Ṣé irú ẹ̀ ló yẹ kó wá gbà mí nímọ̀ràn? Òun náà ṣá máa ń ṣàṣìṣe!’ Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a lè má gba ìmọ̀ràn náà, ká sì fọ̀rọ̀ lọ ẹni tó máa sọ ohun táá bá wa lára mu. w22.02 8-9 ¶2-4
Wednesday, October 25
Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.—Àìsá. 30:15.
Nínú ayé tuntun, àwọn nǹkan kan lè mú kó ṣòro fún wa láti fara mọ́ ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì. Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn pé àwọn ò rí oúnjẹ táwọn ń gbádùn ní Íjíbítì jẹ mọ́, wọn ò sì mọyì mánà tí Jèhófà pèsè fún wọn. (Nọ́ń. 11:4-6; 21:5) Ṣé àwa náà lè nírú èrò yẹn lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá ti kọjá? A ò mọ bí iṣẹ́ tá a máa ṣe ti máa pọ̀ tó ká tó lè sọ ayé di Párádísè. Ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ tá a máa ṣe pọ̀ gan-an, nǹkan sì lè má rọrùn fún wa níbẹ̀rẹ̀. Ṣé àwa náà máa ráhùn nípa nǹkan tí Jèhófà bá pèsè fún wa nígbà yẹn? Ohun kan tó dájú ni pé: Tá a bá mọyì àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè fún wa báyìí, á rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá dìgbà yẹn. w22.02 7 ¶18-19
Thursday, October 26
[Wọn]yóò di aṣọ Júù kan mú . . . ṣinṣin, wọ́n á sì sọ pé: “A fẹ́ bá yín lọ.”—Sek. 8:23.
Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Sekaráyà 8:23, àwọn ọ̀rọ̀ náà “Júù kan” àti “yín” ń tọ́ka sí àwọn èèyàn kan náà, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù sáyé. (Róòmù 2:28, 29) Gbólóhùn náà “ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” ń tọ́ka sí àwọn àgùntàn mìíràn. Wọ́n “di” àwọn ẹni àmì òróró “mú ṣinṣin,” ìyẹn ni pé wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìjọsìn mímọ́. Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìsíkíẹ́lì 37:15-19, 24, 25 ṣẹ, Jèhófà mú kí àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn máa ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ nípa igi méjì. Àwọn tí wọ́n nírètí àtigbé lọ́run ni igi “Júdà” ṣàpẹẹrẹ (ìyẹn ẹ̀yà tí wọ́n ti máa ń yan àwọn ọba Ísírẹ́lì), nígbà tí igi “Éfúrémù” ṣàpẹẹrẹ àwọn tó nírètí àtigbé ayé. Jèhófà máa mú kí àwùjọ méjèèjì yìí wà níṣọ̀kan kí wọ́n lè di “igi kan ṣoṣo.” Ìyẹn ni pé wọ́n á máa ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan, wọ́n á sì jẹ́ kí Jésù Kristi Ọba máa darí àwọn.—Jòh. 10:16. w22.01 22 ¶9-10
Friday, October 27
Kí ẹ rí i pé ẹ ò ṣe òdodo yín níwájú àwọn èèyàn, torí kí wọ́n lè rí yín.—Mát. 6:1.
Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń fún àwọn tálákà lọ́rẹ àmọ́ tí wọ́n ń fẹ́ káwọn èèyàn rí wọn, kí wọ́n lè máa yìn wọ́n. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe yìí dáa, Jèhófà ò tẹ́wọ́ gbà á. (Mát. 6:2-4) Tá a bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ la ní ìwà rere, a ò ní máa ṣe nǹkan fáwọn èèyàn torí ká lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn. Torí náà, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Tí mo bá rí i pé ó yẹ kí n ṣe nǹkan fáwọn èèyàn, ṣé mo máa ń ṣe é? Kí nìdí tí mo fi ń ṣe rere fáwọn èèyàn?’ Gbogbo ìgbà ni ẹ̀mí Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́, kò sì sígbà tí ò lè ràn wá lọ́wọ́. (Jẹ́n. 1:2) Torí náà, gbogbo ìwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní ló yẹ kó máa hàn nínú ìgbésí ayé wa. Bí àpẹẹrẹ, Jémíìsì sọ pé: “Ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Jém. 2:26) Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ téèyàn ò bá ní gbogbo apá yòókù tí èso tẹ̀mí pín sí. Gbogbo ìgbà tá a bá ń fi èso tẹ̀mí hàn là ń fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí wa. w22.03 11-12 ¶14-16
Saturday, October 28
Bíi ti Ẹni Mímọ́ tó pè yín, kí ẹ̀yin náà di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín.—1 Pét. 1:15.
A lè máa kópa déédéé nínú ìjọsìn Jèhófà, ká sì máa ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere. Àmọ́ àpọ́sítélì Pétérù sọ ohun pàtàkì kan tó yẹ káwa Kristẹni ṣe. Kí Pétérù tó rọ̀ wá pé ká jẹ́ mímọ́ nínú gbogbo ìwà wa, ó sọ pé: “Ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́.” (1 Pét. 1:13) Iṣẹ́ wo ló ń sọ? Pétérù sọ pé àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin Kristi máa “ ‘kéde káàkiri [nípa] àwọn ọlá ńlá’ Ẹni tó pè” wọ́n. (1 Pét. 2:9) Ká sòótọ́, gbogbo àwọn Kristẹni ló láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù yìí, tó sì ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní jù lọ. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé àwa èèyàn mímọ́ ń fìtara wàásù, a sì ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn! (Máàkù 13:10) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ yìí, ìyẹn á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa. A sì máa fi hàn pé a fẹ́ “jẹ́ mímọ́” nínú gbogbo ìwà wa. w21.12 13 ¶18
Sunday, October 29
Tí ẹ bá dárí ohunkóhun ji ẹnikẹ́ni, èmi náà ṣe bẹ́ẹ̀.—2 Kọ́r. 2:10.
Ohun tó dáa ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń rò nípa àwọn ará. Ó mọ̀ pé tẹ́nì kan bá ṣàṣìṣe, ìyẹn ò sọ ẹni náà dẹni burúkú. Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, ibi tí wọ́n dáa sí ló sì máa ń wò. Táwọn ará bá ṣe ohun tí kò tọ́, ó mọ̀ pé kò wù wọ́n kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì mọ̀ pé ó yẹ kóun ràn wọ́n lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká wo bí Pọ́ọ̀lù ṣe ran àwọn arábìnrin méjì kan lọ́wọ́ ní ìjọ tó wà ní Fílípì. (Fílí. 4:1-3) Ó jọ pé èdèkòyédè kan wáyé láàárín Yúódíà àti Síńtíkè, ìyẹn ò sì jẹ́ kí àárín wọn gún mọ́. Pọ́ọ̀lù ò le koko mọ́ wọn, kò sì dá wọn lẹ́jọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ibi tí wọ́n dáa sí ló wò. Olóòótọ́ làwọn arábìnrin yìí, èèyàn dáadáa làwọn ará sì mọ̀ wọ́n sí. Pọ́ọ̀lù náà mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn. Ohun tí Pọ́ọ̀lù mọ̀ nípa wọn yìí ló mú kó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n yanjú aáwọ̀ náà kí àárín wọn lè pa dà gún. Torí pé ibi táwọn ará dáa sí ni Pọ́ọ̀lù máa ń wò, ìyẹn jẹ́ kó túbọ̀ láyọ̀, ó sì jẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín òun àtàwọn ará túbọ̀ lágbára. w22.03 30 ¶16-18
Monday, October 30
Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.—Sm. 34:18.
Àlàáfíà tí Jèhófà ń fún wa máa ń jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀, ká sì ronú lọ́nà tó tọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Luz fi hàn pé bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Ó sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé mo dá wà. Nígbà míì, ó máa ń jẹ́ kí n ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ mi. Àmọ́ tó bá ti ń ṣe mí bẹ́ẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára mi fún Jèhófà. Tí mo bá ti gbàdúrà, ara máa ń tù mí gan-an.” Bá a ṣe rí i nínú ìrírí arábìnrin yìí, àdúrà lè mú kí ọkàn tiwa náà balẹ̀. (Fílí. 4:6, 7) A mọ̀ pé Jèhófà àti Jésù máa tu àwa náà nínú tí èèyàn wa kan bá kú. Torí pé Jèhófà àti Jésù máa ń fàánú hàn sí wa, àwa náà máa ń fàánú hàn sáwọn tá à ń wàásù fún, tá a sì ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó ń tù wá nínú bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà àti Jésù mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, wọ́n ń bá wa kẹ́dùn torí àwọn àìléra wa, wọ́n sì ń fẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro tá a bá kojú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa lo àwọn nǹkan tá a ti kọ́ títí dìgbà tí Jèhófà máa “nu gbogbo omijé kúrò ní ojú” wa!—Ìfi. 21:4. w22.01 15 ¶7; 19 ¶19-20
Tuesday, October 31
Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé, torí ẹnubodè tó lọ sí ìparun fẹ̀, ọ̀nà ibẹ̀ gbòòrò, àwọn tó ń gba ibẹ̀ wọlé sì pọ̀.—Mát. 7:13.
Ẹnubodè méjì ni Jésù sọ pé ó wà, ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ẹnubodè méjèèjì sì já sí. Ọ̀nà àkọ́kọ́ “fẹ̀,” ọ̀nà kejì sì rí “tóóró.” (Mát. 7:14) Àmọ́ kò sí ọ̀nà kẹta. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu ọ̀nà tóun máa gbà. Ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé wa nìyẹn torí òun ló máa sọ bóyá a máa jèrè ìyè àìnípẹ̀kun àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gba ọ̀nà tó “fẹ̀” yẹn kọjá torí pé ó rọrùn gbà. Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà lójú ọ̀nà náà, wọ́n sì ń ṣe ohun táwọn tó ń rìn lójú ọ̀nà yẹn ń ṣe. Wọn ò mọ̀ pé Sátánì ló ń fa àwọn èèyàn sójú ọ̀nà yẹn àti pé ikú ló máa gbẹ̀yìn gbogbo àwọn tó ń rin ojú ọ̀nà náà. (1 Kọ́r. 6:9, 10; 1 Jòh. 5:19) Jésù sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀nà tó “fẹ̀” àti èyí tó rí “tóóró.” Ó ní díẹ̀ làwọn tó ń rìn lójú ọ̀nà tóóró yẹn. Kí nìdí? Nínú ẹsẹ tó tẹ̀ lé e, Jésù sọ ohun tó fà á, ó ní ká yẹra fáwọn wòlíì èké.—Mát. 7:15. w21.12 22-23 ¶3-5