November
Wednesday, November 1
Jèhófà máa kọ́ gbogbo wọn.—Jòh. 6:45.
Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Jèhófà máa ń gbà ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa mú sùúrù táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ burúkú sí ẹ lóde ẹ̀rí. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń jẹ́ kó o rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o lè kà táá wọ onílé lọ́kàn. Bákan náà, ó ti fún ẹ lókun kó o lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó báwọn èèyàn ò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ yín. (Jer. 20:7-9) Ọ̀nà míì tá à ń gbà jàǹfààní oore Jèhófà ni pé ó ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Láwọn ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀, a máa ń wo àwọn àṣefihàn àtàwọn fídíò tó dá lórí ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Wọ́n sì máa ń rọ̀ wá pé ká lo àwọn àbá yẹn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó lè kọ́kọ́ ṣòro fún wa láti lo àwọn ọ̀nà tuntun tá à ń gbà wàásù, àmọ́ tá a bá gbìyànjú ẹ̀ wò, a lè wá rí i pé àwọn ọ̀nà yẹn gbéṣẹ́ gan-an ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Láwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa, wọ́n máa ń rọ̀ wá pé ká lo àwọn ọ̀nà tuntun tá ò lò rí láti wàásù. Ẹ̀rù lè máa bà wá láti lo àwọn ọ̀nà tuntun yìí, àmọ́ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bù kún wa. w21.08 27 ¶5-6
Thursday, November 2
Ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ, torí pé àwọn ọjọ́ burú.—Éfé. 5:16.
Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará ìjọ Kọ́ríńtì, ó fún wọn ní ìbáwí tó le. Lẹ́yìn náà, ó rán Títù sí wọn kó lè mọ bí lẹ́tà náà ṣe rí lára wọn. Ẹ wo bínú ẹ̀ ṣe máa dùn tó nígbà tó gbọ́ pé wọ́n ti ṣiṣẹ́ lórí ohun tó bá wọn sọ! (2 Kọ́r. 7:6, 7) Ẹ̀yin alàgbà máa fi hàn pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù tẹ́ ẹ bá ń wà pẹ̀lú àwọn ará. Ọ̀nà kan tẹ́ ẹ lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kẹ́ ẹ máa tètè dé sípàdé kẹ́ ẹ lè bá àwọn ará sọ̀rọ̀ dáadáa. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè má ju ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ tẹ́ ẹ máa fi gba arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó nílò ìṣírí níyànjú. (Róòmù 1:12) Alàgbà tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù tún máa ń lo Bíbélì láti fún àwọn ará níṣìírí, ó sì fi ń dá wọn lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń gbóríyìn fún wọn. Tó bá fẹ́ gba ẹnì kan nímọ̀ràn, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló máa ń lò. Ó máa jẹ́ kí ẹni náà mọ ohun tó yẹ kó ṣiṣẹ́ lé lórí, síbẹ̀, kò ní le koko jù kó lè rọrùn fún ẹni náà láti gba ìmọ̀ràn yẹn.—Gál. 6:1. w22.03 28-29 ¶11-12
Friday, November 3
A ní ìṣúra yìí nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe, kí agbára tó kọjá ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kó má sì jẹ́ látọ̀dọ̀ wa.—2 Kọ́r. 4:7.
Lónìí, Jèhófà ń fún àwa èèyàn ẹ̀ ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” ká lè máa fòótọ́ ọkàn sìn ín nìṣó. Ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà ń fún wa lókun ni nípasẹ̀ àdúrà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú nínú Éfésù 6:18 pé ká máa gbàdúrà sí Ọlọ́run “ní gbogbo ìgbà.” Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà á gbọ́ àdúrà wa, á sì fún wa lókun. Nígbà míì, nǹkan lè tojú sú wa tàbí ká má mọ ohun tá a fẹ́ sọ nínú àdúrà, àmọ́ Jèhófà rọ̀ wá pé ká yíjú sí òun kódà bá ò bá tiẹ̀ mọ bá a ṣe fẹ́ ṣàlàyé ohun tó ń ṣe wá. (Róòmù 8:26, 27) Jèhófà tún máa ń fún wa lókun nípasẹ̀ Bíbélì. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa náà lè rí okun àti ìtùnú gbà látinú Ìwé Mímọ́. (Róòmù 15:4) Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, Jèhófà máa tipasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ mú ká túbọ̀ lóye bí Ìwé Mímọ́ ṣe bá ipò wa mu.—Héb. 4:12. w21.05 22 ¶8-10
Saturday, November 4
Ọlọ́run ń fún yín lágbára, ó ń mú kó wù yín láti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń fún yín ní agbára láti ṣe é.—Fílí. 2:13.
A mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa kọ́ni, àmọ́ àwọn nǹkan kan wà tó lè mú kó ṣòro fún wa láti ṣe tó bá a ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. Àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ sí wa tí ò ní jẹ́ ká ṣe tó bá a ṣe fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn akéde kan ti dàgbà, àwọn míì sì ń ṣàìsàn. Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, rántí pé ní báyìí, a ti lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látorí fóònù, torí náà, o lè wàásù fẹ́nì kan kó o sì máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹ̀ látinú ilé ẹ! Nǹkan míì ni pé àwọn míì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ wọn kì í sí nílé lásìkò tá a máa ń jáde òde ẹ̀rí. Ó ṣeé ṣe kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ráyè láàárọ̀ kùtù tàbí lọ́wọ́ alẹ́. Ṣé o lè ṣètò àkókò ẹ láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lásìkò tí wọ́n máa ráyè? Ó ṣe tán, alẹ́ ni Jésù kọ́ Nikodémù lẹ́kọ̀ọ́ torí àsìkò tí Nikodémù ráyè nìyẹn.—Jòh. 3:1, 2. w21.07 5 ¶10-11
Sunday, November 5
Àwọn èèyàn yìí ń fi ẹnu wọn sún mọ́ mi, wọ́n sì ń fi ètè wọn bọlá fún mi, àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi.—Àìsá. 29:13.
Ó ya àwọn ọmọlẹ́yìn Jòhánù Arinibọmi lẹ́nu pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kì í gbààwẹ̀. Jésù ṣàlàyé fún wọn pé kò sídìí tí àwọn ọmọlẹ́yìn òun fi máa gbààwẹ̀ nígbà tóun ṣì wà láyé. (Mát. 9:14-17) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Farisí àtàwọn alátakò Jésù bẹnu àtẹ́ lù ú torí pé kò tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn. Inú bí wọn nígbà tó wo àwọn èèyàn sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. (Máàkù 3:1-6; Jòh. 9:16) Àwọn èèyàn yìí gbà pé àwọn ń pa Sábáàtì mọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọn ò rí ohun tó burú nínú bí wọ́n ṣe ń ṣòwò nínú tẹ́ńpìlì. Wọ́n gbaná jẹ nígbà tí Jésù dẹ́bi fún wọn nítorí òwò tí wọ́n ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì. (Mát. 21:12, 13, 15) Bákan náà, àwọn tí Jésù wàásù fún nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárẹ́tì bínú gidigidi nígbà tó sọ ìtàn kan tó jẹ́ kó hàn gbangba pé onímọtara-ẹni-nìkan ni wọ́n, wọn ò sì nígbàgbọ́. (Lúùkù 4:16, 25-30) Ohun tí wọ́n retí pé kí Jésù ṣe àmọ́ tí ò ṣe mú kí ọ̀pọ̀ kọsẹ̀.—Mát. 11:16-19. w21.05 5-6 ¶13-14
Monday, November 6
A mọ àwọn ọgbọ́n rẹ̀.—2 Kọ́r. 2:11.
Jèhófà jẹ́ kí àkọsílẹ̀ àwọn tó gbéra ga tàbí tó ṣojúkòkòrò wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì, ká lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, ká má bàa ṣe bíi tiwọn. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó lójú kòkòrò, Sátánì Èṣù ló máa kọ́kọ́ wá sí wa lọ́kàn. Ó dájú pé Sátánì ní ọ̀pọ̀ àǹfààní tẹ́lẹ̀ torí pé ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì Jèhófà ni. Àmọ́, ìyẹn ò tó o. Ó fẹ́ káwọn míì máa jọ́sìn òun, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà nìkan ni ìjọsìn tọ́ sí. Sátánì fẹ́ ká dà bí òun, ó fẹ́ ká máa ṣojúkòkòrò, kí ohun tá a ní má sì tẹ́ wa lọ́rùn. Àtorí Éfà ló ti bẹ̀rẹ̀. Jèhófà pèsè gbogbo ohun tí Éfà àti ọkọ rẹ̀ nílò lọ́pọ̀ yanturu. Kódà, ó sọ fún wọn pé wọ́n lè jẹ “èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà” Édẹ́nì àyàfi ẹyọ kan. (Jẹ́n. 2:16) Síbẹ̀, Sátánì mú kí ojú Éfà wọ èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà, ìyẹn sì mú kó ronú pé òun gbọ́dọ̀ jẹ nínú ẹ̀. Éfà ò mọyì gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe fún un, ṣe ló tún ń nàgà fún ohun tí ò lẹ́tọ̀ọ́ sí. Àwa náà mọ ohun tíyẹn yọrí sí. Éfà dẹ́ṣẹ̀, ó sì kú nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.—Jẹ́n. 3:6, 19. w21.06 14 ¶2-3; 17 ¶9
Tuesday, November 7
Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.—Jẹ́n. 1:28.
Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí Ádámù àti Éfà bímọ, kí wọ́n sì máa bójú tó ilẹ̀ ayé. Ká sọ pé Ádámù àti Éfà ṣègbọràn sí Jèhófà ni, tí wọ́n sì ṣe ohun tó fẹ́, àwọn ọmọ wọn ò bá wà nínú ìdílé Ọlọ́run títí láé. Ipò pàtàkì ni Ádámù àti Éfà wà nínú ìdílé Jèhófà, ó sì buyì kún wọn gan-an. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 8:5 àti àlàyé ìsàlẹ̀, Dáfídì sọ nípa àwa èèyàn pé: “O mú kó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì, o sì fi ògo àti ọlá ńlá dé e ládé.” Òótọ́ ni pé àwa èèyàn ò ní okun àti agbára bíi tàwọn áńgẹ́lì, ọgbọ́n wa ò sì tó tiwọn. (Sm. 103:20) Síbẹ̀, ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ kó hàn kedere pé ìwọ̀nba “díẹ̀” làwa èèyàn fi rẹlẹ̀ sí àwọn áńgẹ́lì. Ó bani nínú jẹ́ pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, Jèhófà sì kọ̀ wọ́n lọ́mọ. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn ṣàkóbá gan-an fáwọn àtọmọdọ́mọ wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣàìgbọràn, ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fáráyé ò yí pa dà. Bópẹ́ bóyá, àwọn onígbọràn máa di ọmọ ẹ̀ títí láé. w21.08 2-3 ¶2-4
Wednesday, November 8
“Kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun tàbí nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,” ni Jèhófà . . . wí.—Sek. 4:6.
Lónìí, ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà làwọn èèyàn ń ṣenúnibíni sí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ń gbé lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Wọ́n lè fàṣẹ ọba mú wọn, kí wọ́n sì mú wọn “lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba” kó lè jẹ́ ẹ̀rí fáwọn alákòóso náà. (Mát. 10:17, 18) Àtakò táwọn ará wa kan ń dojú kọ tún yàtọ̀ síyẹn. Lóòótọ́, orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fàyè gbà wá láti sin Jèhófà ni wọ́n ń gbé, àmọ́ ṣe làwọn mọ̀lẹ́bí wọn ń fúngun mọ́ wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ sin Jèhófà mọ́. (Mát. 10:32-36) Lọ́pọ̀ ìgbà, táwọn mọ̀lẹ́bí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ta kò wọ́n bá ti rí i pé pàbó ni gbogbo ìsapá àwọn já sí, wọn kì í ta kò wọ́n mọ́. Kódà, àwọn kan tó hùwà ìkà sáwọn ará wa kan kí wọ́n má bàa jọ́sìn Jèhófà mọ́ ti wá di Ẹlẹ́rìí tó ń fìtara wàásù. Torí náà, tí wọ́n bá ń ta kò ẹ́, má jẹ́ kíyẹn mú kó o fi Jèhófà sílẹ̀! Má bẹ̀rù. Jèhófà máa wà pẹ̀lú ẹ, ó sì tún máa fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́, torí náà kò sídìí fún ẹ láti bẹ̀rù! w22.03 16 ¶8
Thursday, November 9
Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun tó burú.—Sm. 97:10.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kórìíra “ojú ìgbéraga, ahọ́n èké àti ọwọ́ tó ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.” (Òwe 6:16, 17) Ó tún “kórìíra àwọn tó ń hu ìwà ipá àti ìwà ẹ̀tàn.” (Sm. 5:6) Nítorí àwọn ìwà burúkú yìí ni Ọlọ́run ṣe pa àwọn èèyàn burúkú ìgbà ayé Nóà run torí wọ́n fi ìwà ipá wọn kún ayé. (Jẹ́n. 6:13) Jèhófà tún gba ẹnu wòlíì Málákì sọ pé òun kórìíra àwọn tí wọ́n ń dọ́gbọ́n kọ ìyàwó wọn sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ìyàwó náà ò hùwà àìṣòótọ́ kankan. Ọlọ́run ò tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn, ó sì máa dá wọn lẹ́jọ́ nítorí ìwà wọn. (Mál. 2:13-16; Héb. 13:4) Jèhófà fẹ́ ká “kórìíra ohun búburú.” (Róòmù 12:9) Tẹ́nì kan bá “kórìíra” ohun kan, ẹni náà á ka nǹkan náà sí ohun ẹ̀gbin, ìyẹn ni pé ó máa kórìíra nǹkan ọ̀hún gidigidi débi pé á máa rí i lára. Torí náà, ó yẹ kó máa rí wa lára tá a bá ti fẹ́ máa ronú nípa ohun tí Jèhófà sọ pé ó burú. w22.03 4-5 ¶11-12
Friday, November 10
Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó ń retí rẹ̀.—Àìsá. 30:18.
Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún gbogbo wa. Gbogbo àwọn tó bá ń fi sùúrù dúró de Jèhófà máa gba ọ̀pọ̀ ìbùkún nísinsìnyí àti nínú ayé tuntun. Tá a bá dénú ayé tuntun, kò ní sídìí tó fi yẹ ká máa fara da àwọn ìṣòro tá à ń kojú lónìí yìí mọ́. Kò sẹ́ni tó máa hùwà àìdáa sí wa, kò sì ní sí ìrora èyíkéyìí mọ́. (Ìfi. 21:4) Tó bá dìgbà yẹn, a ò ní máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tá a nílò mọ́ torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa wà fún gbogbo wa. (Sm. 72:16; Àìsá. 54:13) Ẹ ò rí i pé àsìkò yẹn máa lárinrin gan-an! Ní báyìí, Jèhófà ń múra wa sílẹ̀ láti gbé lábẹ́ Ìjọba yẹn ní ti pé ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò dáa, ká sì láwọn ìwà tó ń múnú ẹ̀ dùn. Torí náà má jẹ́ kó sú ẹ, má sì fi Jèhófà sílẹ̀. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan la máa gbádùn nínú ayé tuntun! Bá a ṣe ń dúró dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká máa fayọ̀ dúró de Jèhófà ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ohun tí Jèhófà ṣèlérí ló máa ṣe lásìkò tó ti pinnu gẹ́lẹ́! w21.08 13 ¶17-19
Saturday, November 11
Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa pín ohun tí ẹ ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, torí inú Ọlọ́run máa ń dùn gan-an sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀.—Héb. 13:16.
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí àwọn ará ní Jùdíà gba lẹ́tà látọ̀dọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sá kúrò nílé wọn, wọ́n fi iṣẹ́ wọn títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí kì í ṣe Kristẹni sílẹ̀, wọ́n sì “bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.” (Mát. 24:16) Kò sí àní-àní pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́ lásìkò yẹn. Tó bá jẹ́ pé wọ́n ti ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò ṣáájú àkókò yẹn pé kí wọ́n máa ran ara wọn lọ́wọ́, ó máa rọrùn fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ níbi tuntun tí wọ́n lọ. Kì í ṣe gbogbo ìgbà làwọn ará wa máa ń sọ nǹkan tí wọ́n nílò fún wa. Torí náà, jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́. Ó dájú pé o mọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ ẹ tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Wọn kì í jẹ́ ká rò pé à ń yọ àwọn lẹ́nu. A mọ̀ pé wọ́n ṣeé fọkàn tán àti pé kò sígbà tá a ní kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ tí wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì dájú pé àwa náà máa fẹ́ ṣe bíi tiwọn! w22.02 23-24 ¶13-15
Sunday, November 12
Ẹ . . . pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.—Éfé. 4:3.
Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ ìjọ àti àyíká la ti tún tò. Tí wọ́n bá ní ká lọ dara pọ̀ mọ́ ìjọ tuntun kan, ó lè ṣòro fún wa láti fi àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé wa sílẹ̀. Ṣé Jèhófà ló sọ ìjọ táwọn alàgbà yẹn máa yan akéde kọ̀ọ̀kan sí? Rárá. Torí náà, ìyẹn lè jẹ́ kó ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé ohun tí wọ́n bá sọ. Àmọ́ Jèhófà fọkàn tán àwọn alàgbà yẹn pé wọ́n á ṣe ìpinnu tó tọ́ nírú àwọn ipò yẹn, ó sì yẹ káwa náà fọkàn tán wọn. Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé ohun táwọn alàgbà bá sọ, kódà tí ìpinnu tí wọ́n ṣe ò bá tẹ́ wa lọ́rùn? Ìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, á jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run. Tí gbogbo àwọn ará bá ń fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé ìpinnu ìgbìmọ̀ alàgbà ìjọ wọn, ìyẹn á jẹ́ kí ìjọ túbọ̀ lágbára. (Héb. 13:17) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a máa fi hàn pé a fọkàn tán Jèhófà tá a bá fọkàn tán àwọn tó ní kó máa ṣàbójútó wa, tá a sì ń tẹ̀ lé ohun tí wọ́n bá sọ.—Ìṣe 20:28. w22.02 4-5 ¶9-10
Monday, November 13
Máa tẹra mọ́ kíkàwé fún ìjọ, máa gbani níyànjú, kí o sì máa kọ́ni.—1 Tím. 4:13.
Tó o bá jẹ́ arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi, ó yẹ kó o sapá kó o lè sunwọ̀n sí i nínú bó o ṣe ń kọ́ni nínú ìjọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé tó o bá túbọ̀ já fáfá nínú bó o ṣe ń kàwé àti bó o ṣe ń kọ́ni nínú ìjọ, ìyẹn á ṣe àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ láǹfààní. (1 Tím. 4:15) Fi ṣe àfojúsùn ẹ pé wàá ka gbogbo ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni, wàá sì fi àwọn àbá tó wà nínú ẹ̀ sílò. Tó o bá ka ẹ̀kọ́ kan tán, fi dánra wò dáadáa nílé, kó o wá lo àwọn àbá inú ẹ̀ tó o bá níṣẹ́ nípàdé. Yàtọ̀ síyẹn, o lè gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn tàbí lọ́wọ́ àwọn alàgbà míì tí wọ́n “ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.” (1 Tím. 5:17) Àmọ́ o, kì í ṣe bá a ṣe máa fi àwọn àbá náà sílò nìkan ló yẹ kó jẹ wá lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará ró, kó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn débi tí wọ́n á fi gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ àtàwọn tó ń tẹ́tí sí ẹ á túbọ̀ láyọ̀. w21.08 24 ¶17
Tuesday, November 14
Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.—Fílí. 2:3.
Tá a bá gbà pé àwọn míì sàn jù wá lọ, a ò ní máa fi ara wa wé àwọn míì tí wọ́n ní ẹ̀bùn táwa ò ní. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe làá mọyì wọn pàápàá tí wọ́n bá ń lo ẹ̀bùn wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Nípa bẹ́ẹ̀, àlàáfíà, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan máa jọba nínú ìjọ. Tá ò bá fẹ́ máa jowú tàbí ṣe ìlara, ó ṣe pàtàkì ká mọ̀wọ̀n ara wa. Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, a ò ní máa ṣe bíi pé àwa la gbọ́n jù tàbí pé a mọ nǹkan ṣe ju àwọn míì lọ. Dípò bẹ́ẹ̀, àá máa wá bá a ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, ká ní arákùnrin kan mọ bí wọ́n ṣe ń sọ àsọyé tó máa ń wọni lọ́kàn, a lè bi í nípa bó ṣe máa ń múra sílẹ̀. Tí arábìnrin kan bá mọ oúnjẹ sè, a lè ní kó kọ́ wa káwa náà lè sunwọ̀n sí i. w21.07 16 ¶8-9
Wednesday, November 15
[Jèhófà] kì í ṣe ojúsàájú.—Diu. 32:4.
Nínú ìwé Nọ́ńbà, a kà nípa bí Jèhófà ṣe ní kí wọ́n pa ọmọ Ísírẹ́lì kan torí pé ó ń ṣa igi lọ́jọ́ Sábáàtì. Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún méjì lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nínú Sámúẹ́lì kejì pé Jèhófà dárí ji Ọba Dáfídì tó bá ìyàwó oníyàwó sùn, tó sì tún pa ọkọ ẹ̀. (Nọ́ń. 15:32, 35; 2 Sám. 12:9, 13) Torí náà, a lè máa rò pé, ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi dárí ji Dáfídì tó ṣàgbèrè tó sì tún pààyàn, àmọ́ tó ní kí wọ́n pa ọkùnrin tó dá ẹ̀ṣẹ̀ tó jọ pé kò tó nǹkan?’ Kì í ṣe gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn kan ni Bíbélì máa ń sọ. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ fún wa pé nígbà tí Dáfídì dẹ́ṣẹ̀, ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. (Sm. 51:2-4) Àmọ́ irú èèyàn wo ni ọkùnrin tó rú òfin Sábáàtì yẹn? Ṣé ó kábàámọ̀ ohun tó ṣe? Ṣé ó ti máa ń rú àwọn òfin Jèhófà tẹ́lẹ̀? Tí wọ́n bá kìlọ̀ fún un, ṣé ó máa ń gbọ́? Bíbélì ò sọ fún wa. Ṣùgbọ́n, gbogbo nǹkan tá a mọ̀ nípa Jèhófà jẹ́ kó dá wa lójú pé ó jẹ́ “adúróṣinṣin nínú gbogbo ohun tó ń ṣe.”—Sm. 145:17. w22.02 2-3 ¶3-4
Thursday, November 16
Ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn.—Òwe 11:2.
Ẹni tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa ń dín ohun tó lè ṣe kù. Ìyẹn á mú kó máa láyọ̀, kó má sì dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. A lè fi ẹni tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ wé ẹni tó ń rìn lórí ilẹ̀ tó ń yọ̀. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ní láti rọra máa rìn kó má bàa yọ̀ ṣubú. Òótọ́ ni pé kò ní yára rìn mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Àmọ́, kò ní dúró sójú kan. Lọ́nà kan náà, ẹni tó bá mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa mọ̀gbà tó yẹ kóun rọra máa rìn kóun lè máa báṣẹ́ lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Fílí. 4:5) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Básíláì tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin (80) ọdún nígbà tí Ọba Dáfídì sọ pé kó wá di ìjòyè láàfin òun. Básíláì kọ̀ torí pé ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀. Ó mọ̀ pé ìwọ̀nba lòun lè ṣe. Básíláì wá dábàá Kímúhámù tó jẹ́ ọ̀dọ́ pé kó tẹ̀ lé ọba dípò òun. (2 Sám. 19:35-37) Bíi ti Básíláì, inú àwọn arákùnrin tó jẹ́ àgbàlagbà máa ń dùn láti jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa bójú tó àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan. w21.09 10 ¶6-7
Friday, November 17
Kò sẹ́ni tó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba, kò sì sẹ́ni tó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ṣí i payá fún.—Lúùkù 10:22.
Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti gbà pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà? Ó máa ń ṣe àwọn kan lára wa bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé bàbá tó bí wa kì í fìfẹ́ hàn sí wa, ó lè ṣòro fún wa láti gbà pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà. Síbẹ̀, ó tuni nínú láti mọ̀ pé Jèhófà mọ bó ṣe ń ṣe wá àti ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀ lára wa. Ó fẹ́ ká sún mọ́ òun. Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ ẹ̀ fi gbà wá níyànjú pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.” (Jém. 4:8) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ṣèlérí pé òun máa jẹ́ Baba tó ju baba lọ fún wa. Jésù lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Jésù mọ Jèhófà dáadáa, ó sì fìwà jọ ọ́ débi tó fi sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.” (Jòh. 14:9) Bí ẹ̀gbọ́n kan ṣe máa ń kọ́ àwọn àbúrò ẹ̀, Jésù ti jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà ká sì máa ṣègbọràn sí i. Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tá a lè máa yẹra fún ká lè máa múnú Jèhófà dùn àti bá a ṣe lè rí ojúure ẹ̀. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, bí Jésù ṣe gbé ìgbésí ayé ẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ká rí i pé Jèhófà jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti onínúure. w21.09 21 ¶4-5
Saturday, November 18
Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tó wà níkàáwọ́ yín.—1 Pét. 5:2.
Àwa èèyàn Jèhófà ń jọ́sìn rẹ̀ níṣọ̀kan. Jèhófà ti gbé iṣẹ́ ńlá kan lé àwọn alàgbà lọ́wọ́ pé kí wọ́n jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́. Tí Kristẹni kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, Jèhófà fẹ́ káwọn alàgbà wò ó bóyá ẹni náà ṣì lè wà nínú ìjọ. Ara ohun tó yẹ kí wọ́n tún wò ni bóyá onítọ̀hún ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Ó lè sọ pé òun ti ronú pìwà dà, àmọ́ ṣé lóòótọ́ ló kórìíra ẹ̀ṣẹ̀ tó dá? Ṣé ó ti pinnu pé òun ò ní dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́? Tó bá jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ burúkú tó ń bá rìn ló mú kó dá ẹ̀ṣẹ̀ náà, ṣé ó ti pinnu pé òun máa fi àwọn ọ̀rẹ́ náà sílẹ̀? Àwọn alàgbà máa gbàdúrà sí Jèhófà, wọ́n á gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, wọ́n á wo ohun tí Bíbélì sọ lórí ẹ̀, wọ́n á sì wò ó bóyá ẹlẹ́ṣẹ̀ náà kábàámọ̀ ohun tó ṣe. Lẹ́yìn náà, wọ́n á pinnu bóyá oníwà àìtọ́ náà ṣì lè wà nínú ìjọ. Láwọn ipò kan, wọ́n á yọ onítọ̀hún kúrò nínú ìjọ.—1 Kọ́r. 5:11-13. w22.02 5 ¶11-12
Sunday, November 19
Ẹ fi ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.—Kól. 3:10.
Bóyá ó ti pẹ́ tá a ti ṣèrìbọmi tàbí kò tíì pẹ́, gbogbo wa la fẹ́ máa hùwà tó máa múnú Jèhófà dùn. Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa kíyè sí ohun táà ń rò lọ́kàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìwà wa lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà la máa ń ro èròkerò, ó lè jẹ́ ká sọ ohun tí ò dáa tàbí ṣe ohun tí ò dáa. (Éfé. 4:17-19) Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ohun tó dáa là ń rò lọ́kàn, ohun tó máa múnú Jèhófà dùn làá máa sọ, tí àá sì máa ṣe. (Gál. 5:16) Àmọ́, kò sí bá a ṣe lè ṣe é tí èròkerò ò ní wá sí wa lọ́kàn. Torí náà, a gbọ́dọ̀ rí i pé a gbé e kúrò lọ́kàn. Kó tó di pé a ṣèrìbọmi, ó ti yẹ ká jáwọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe tí inú Jèhófà ò dùn sí. Àwọn nǹkan tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe nìyẹn ká tó lè bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀. Ká sì tó lè múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀. w22.03 8 ¶1-2
Monday, November 20
Ní gbogbo ọ̀nà, ẹ ti fi hàn pé ẹ jẹ́ mímọ́ nínú ọ̀ràn yìí.—2 Kọ́r. 7:11.
Kì í rọrùn fáwọn alàgbà láti mọ̀ bóyá ẹnì kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn alàgbà ò lè rí ọkàn. Torí náà, wọ́n máa ní láti wá àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé ẹni náà ti yí pa dà, ó sì ti kórìíra ohun tó ṣe. Torí náà, àwọn alàgbà máa ní láti rí ìyípadà nínú bí oníwà àìtọ́ náà ṣe ń ronú, bó ṣe ń hùwà àti bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ̀. Ó lè pẹ́ díẹ̀ kí ẹni náà tó ṣe àwọn àyípadà yìí. Kí ẹnì kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ tó lè fi hàn pé òun ronú pìwà dà, ó gbọ́dọ̀ máa wá sípàdé déédéé, kó sì máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn táwọn alàgbà fún un pé kó máa gbàdúrà, kó sì máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Á tún sapá láti máa yẹra fún ohun tó lè mú kó pa dà sínú ìwà burúkú náà. Tó bá ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ó dájú pé Jèhófà máa dárí jì í, àwọn alàgbà náà sì máa gbà á pa dà sínú ìjọ. w21.10 6 ¶16-18
Tuesday, November 21
O ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère kankan fún ara rẹ tàbí kí o ṣe ohun kan tó dà bí ohunkóhun lókè ọ̀run tàbí ní ayé . . . O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn.—Ẹ́kís. 20:4, 5.
Ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jésù ní fún Jèhófà ló mú kó fi gbogbo ọkàn ẹ̀ sìn ín nígbà tó wà lọ́run àti nígbà tó wà láyé. (Lúùkù 4:8) Ohun tí Jésù sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ náà nìyẹn. Jésù ò lo ère, kò sì sí ìkankan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ olóòótọ́ tó lo ère nínú ìjọsìn wọn. Bíbélì sọ pé Ẹ̀mí ni Ọlọ́run. Torí pé a ò lè rí Jèhófà, kò sí ẹnì kankan tó lè gbẹ́ ère tó jọ Jèhófà láé! (Àìsá. 46:5) Àmọ́, ṣé ó yẹ ká máa ṣe ère àwọn tí wọ́n ń pè ní ẹni mímọ́ ká sì máa gbàdúrà sí wọn? Nínú Òfin Mẹ́wàá tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, inú Òfin kejì ni Jèhófà ti sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní. Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yẹn yé àwọn tó fẹ́ múnú Jèhófà dùn, wọ́n sì mọ̀ pé kò fẹ́ káwọn máa jọ́sìn ère. Àwọn òpìtàn gbà pé Ọlọ́run nìkan ni àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ jọ́sìn. Lónìí, ọ̀nà táwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ gbà jọ́sìn làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbà jọ́sìn. w21.10 19-20 ¶5-6
Wednesday, November 22
Kí ẹni tó wà lórí ilé má sọ̀ kalẹ̀ wá kó ẹrù kúrò nínú ilé rẹ̀.—Mát. 24:17.
Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ń gbé ní Jùdíà nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ pé ‘àwọn ọmọ ogun máa pàgọ́ yí Jerúsálẹ́mù ká.’ (Lúùkù 21:20-24) Ó sọ fún wọn pé tó bá ti ṣẹlẹ̀, kí wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.” Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á sá àsálà. Àmọ́, ìyẹn máa gba pé kí wọ́n filé fọ̀nà wọn sílẹ̀. Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, Ilé Ìṣọ́ kan sọ pé: “Wọ́n filé fọ̀nà wọn sílẹ̀, wọn ò tiẹ̀ kó dúkìá tí wọ́n ní sílé pàápàá. Nítorí pé wọ́n nígbọ̀ọ́kànlé pé Jèhófà yóò dáàbò bo àwọn àti pé yóò pèsè fáwọn, wọ́n fi ìjọsìn rẹ̀ ṣáájú ohunkóhun tó lè jọ pé ó ṣe pàtàkì.” Ilé Ìṣọ́ yẹn kan náà tún sọ pé: “Lọ́jọ́ iwájú, ó ṣeé ṣe ká kojú àwọn àdánwò kan torí ojú tá a fi ń wo nǹkan tara; ṣé àwọn nǹkan yẹn la kà sí pàtàkì jù àbí bí Ọlọ́run ṣe máa gbà wá là? Tó bá dìgbà yẹn, ó lè pọn dandan pé ká ṣe àwọn àyípadà kan, ìyẹn sì lè mú kí nǹkan nira fún wa. Torí náà, ó yẹ ká múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó yẹ ká ṣe.” w22.01 4 ¶7-8
Thursday, November 23
Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ mà ṣeyebíye o, Ọlọ́run!—Sm. 36:7.
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, Jèhófà sọ orúkọ rẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ fún Mósè. Ó sọ pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini.” (Ẹ́kís. 34:6, 7) Àwọn ànímọ́ tí Jèhófà sọ fún Mósè pé òun ní yìí jẹ́ kó mọ̀ pé Ọlọ́run tí ìfẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀ lòun jẹ́. Torí náà, kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀? Nígbà tí Jèhófà ń sọ irú ẹni tí òun jẹ́, kò kàn sọ pé òun ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ nìkan, àmọ́ ohun tó sọ ni pé ‘ìfẹ́ òun tí kì í yẹ̀ pọ̀ gidigidi.’ Gbólóhùn yìí tún fara hàn níbi mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Bíbélì. (Nọ́ń. 14:18; Neh. 9:17; Sm. 86:15; 103:8; Jóẹ́lì 2:13; Jónà 4:2) Kò sẹ́ni tá a máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí fún àfi Jèhófà nìkan ṣoṣo. Ẹ ò rí i pé bí Jèhófà ṣe tẹnu mọ́ ànímọ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run tí ìfẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀ lòun jẹ́. w21.11 2-3 ¶3-4
Friday, November 24
Ẹ yéé ṣàníyàn nípa ẹ̀mí yín.—Mát. 6:25.
Àwọn tọkọtaya lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pétérù àti ìyàwó ẹ̀. Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà sí ọdún kan lẹ́yìn tí Pétérù kọ́kọ́ rí Jésù, ó pọn dandan pé kó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan. Iṣẹ́ apẹja ni Pétérù ń ṣe. Torí náà, nígbà tí Jésù sọ pé kí Pétérù wá di ọmọ ẹ̀yìn òun, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ronú nípa bí òun á ṣe máa gbọ́ bùkátà ìdílé òun. (Lúùkù 5:1-11) Síbẹ̀, Pétérù pinnu pé òun á di ọmọlẹ́yìn Jésù. Ó sì dájú pé ìyàwó ẹ̀ náà tì í lẹ́yìn. Bíbélì jẹ́ ká rí i pé lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, àwọn àsìkò kan wà tí Pétérù àti ìyàwó ẹ̀ jọ rìnrìn àjò láti gbé ìjọ ró. (1 Kọ́r. 9:5) Ó dájú pé àpẹẹrẹ rere tí ìyàwó Pétérù fi lélẹ̀ ló jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀ fàlàlà nínú ìjọ, tó sì tún kọ ìmọ̀ràn táwọn tọkọtaya lè máa tẹ̀ lé sílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. (1 Pét. 3:1-7) Torí náà, kò sí àní-àní pé Pétérù àti ìyàwó ẹ̀ gbà pé òótọ́ ni ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa pèsè fún wọn tí wọ́n bá fi iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn.—Mát. 6:31-34. w21.11 18 ¶14
Saturday, November 25
Ẹ máa fara wé mi.—1 Kọ́r. 11:1.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, ó sì ṣiṣẹ́ kára gan-an nítorí wọn. (Ìṣe 20:31) Àwọn ará náà sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ torí pé ó ń ṣiṣẹ́ kára. Nígbà táwọn alàgbà tó wà ní Éfésù gbọ́ pé àwọn ò ní rí Pọ́ọ̀lù mọ́, ṣe ni wọ́n “bú sẹ́kún.” (Ìṣe 20:37) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ wa nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. (Fílí. 2:16, 17) Àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn fáwọn alàgbà láti ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Kí ló máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ wọn yanjú? Ẹ̀yin alàgbà lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára Pọ́ọ̀lù. Èèyàn bíi tiwa ni. Aláìpé lòun náà, kódà kì í rọrùn fún un láti ṣe ohun tó tọ́ nígbà míì. (Róòmù 7:18-20) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún kojú onírúurú ìṣòro. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kíyẹn mú kóun rẹ̀wẹ̀sì tàbí banú jẹ́. Táwọn alàgbà bá ń fara wé Pọ́ọ̀lù, wọ́n á lè ṣiṣẹ́ wọn yanjú, wọ́n á sì máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń sin Jèhófà. w22.03 26 ¶1-2
Sunday, November 26
Kí ẹ sì máa pa àwọn sábáàtì mi mọ́. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.—Léf. 19:3.
Léfítíkù 19:3 sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa pa Sábáàtì mọ́. Àwa Kristẹni ò tẹ̀ lé Òfin Mósè mọ́, torí náà a kì í pa Sábáàtì mọ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó pa Sábáàtì mọ́, àá sì tún rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àǹfààní tó ṣe wọ́n. Ọjọ́ Sábáàtì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń sinmi kí wọ́n lè ráyè jọ́sìn Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi máa ń lọ sínú sínágọ́gù ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ lọ́jọ́ Sábáàtì kó lè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ẹ́kís. 31:12-15; Lúùkù 4:16-18) Òfin Ọlọ́run tó wà nínú Léfítíkù 19:3 tó sọ pé ká máa ‘pa sábáàtì rẹ̀ mọ́’ yẹ kó mú ká máa wáyè fún ìjọsìn Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa pa àṣẹ náà mọ́? Tó o bá ń wáyè fún ìjọsìn Ọlọ́run, àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà á túbọ̀ gún régé, ìyẹn á sì jẹ́ kó o jẹ́ mímọ́. w21.12 5 ¶13
Monday, November 27
Kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè kí wọ́n ronú pìwà dà, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.—Lúùkù 5:32.
Nígbà tí Jésù wà láyé, onírúurú èèyàn ló bá kẹ́gbẹ́. Ó bá àwọn olówó àtàwọn tó lẹ́nu láwùjọ jẹun, àmọ́ ó tún lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìní àtàwọn tí ò lẹ́nu láwùjọ. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń fàánú hàn sáwọn táwọn èèyàn kà sí “ẹlẹ́ṣẹ̀.” Ohun tí Jésù ṣe yìí mú káwọn kan tó ka ara wọn sí olódodo kọsẹ̀. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, tí ẹ sì ń bá wọn mu?” Jésù wá dá wọn lóhùn pẹ̀lú ohun tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní. (Lúùkù 5:29-31) Ọ̀pọ̀ ọdún kí Mèsáyà tó wá sáyé ni wòlíì Àìsáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní tẹ́tí sí i. Wòlíì náà sọ pé: “Àwọn èèyàn kórìíra rẹ̀, wọ́n sì yẹra fún un . . . Ó dà bí ẹni pé ojú rẹ̀ pa mọ́ fún wa. Wọ́n kórìíra rẹ̀, a sì kà á sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.” (Àìsá. 53:3) Torí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti sọ pé “àwọn èèyàn” máa yẹra fún Mèsáyà, ó yẹ káwọn Júù ìgbà yẹn ti mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní tẹ́tí sí Jésù. w21.05 8-9 ¶3-4
Tuesday, November 28
Jèhófà máa gbé e dìde.—Jém. 5:15.
Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ kan kì í tètè lo ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún wọn. (Jém. 1:22) Àwọn míì ń ṣojúure sáwọn kan torí pé wọ́n jẹ́ olówó. (Jém. 2:1-3) Àwọn kan tún wà tí wọn ò lè kápá ahọ́n wọn. (Jém. 3:8-10) Àwọn Kristẹni yẹn ní ọ̀pọ̀ ìṣòro, àmọ́ Jémíìsì gbà pé wọ́n ṣì lè yí pa dà. Ó gbà wọ́n nímọ̀ràn lọ́nà tó tura, àmọ́ ó sòótọ́ ọ̀rọ̀ fún wọn. Ó sì gba àwọn tí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà kò gún régé níyànjú láti wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn alàgbà. (Jém. 5:13, 14) Ohun tá a rí kọ́: Máa sọ òótọ́ ọ̀rọ̀, àmọ́ má fojú burúkú wo àwọn èèyàn. Ó lè nira fún ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láti lo ìmọ̀ràn inú Bíbélì. (Jém. 4:1-4) Ó lè gba àkókò kí wọ́n tó jáwọ́ nínú ìwà burúkú, kí wọ́n sì fìwà jọ Kristi. Ó yẹ ká fìgboyà sọ ibi tó yẹ kí wọ́n ti ṣàtúnṣe. Ó sì tún yẹ ká máa ní èrò rere, ká fọkàn tán Jèhófà pé á fa àwọn onírẹ̀lẹ̀ wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀, á sì fún wọn ní agbára láti yí ìgbésí ayé wọn pa dà.—Jém. 4:10. w22.01 11 ¶11-12
Wednesday, November 29
Ẹni tó bá di etí rẹ̀ sí igbe aláìní òun fúnra rẹ̀ yóò pè, a kò sì ní dá a lóhùn.—Òwe 21:13.
Kí nìdí táwa Kristẹni fi máa ń fàánú hàn bíi ti Jèhófà? Ìdí ni pé Jèhófà ò ní tẹ́tí sí àdúrà àwọn tí ò bá fàánú hàn. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa. Torí náà, kò yẹ ká fọwọ́ tó le jù mú àwọn èèyàn. Dípò ká dé fìlà má-wo-bẹ̀ tí Kristẹni kan bá ń jìyà, ṣe ló yẹ ká ṣe tán nígbà gbogbo láti tẹ́tí sí “igbe aláìní.” Bákan náà, ó yẹ ká fi ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí sọ́kàn pé: “Ẹni tí kì í ṣàánú kò ní rí àánú gbà nígbà ìdájọ́.” (Jém. 2:13) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tá a sì ń fi sọ́kàn pé àwa náà nílò àánú, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ yá wa lára láti máa fàánú hàn. Ní pàtàkì, ó yẹ ká fàánú hàn tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà bá pa dà sínú ìjọ. Àpẹẹrẹ àwọn tó wà nínú Bíbélì lè jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa fàánú hàn, ká má sì fọwọ́ tó le jù mú àwọn èèyàn. w21.10 12 ¶16-17
Thursday, November 30
Ẹ jókòó síbí, mo fẹ́ lọ sí ọ̀hún yẹn lọ gbàdúrà.—Mát. 26:36.
Ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ ikú Jésù, nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ń parí lọ, Jésù wá ibì kan tó pa rọ́rọ́ kó lè ṣàṣàrò, kó sì gbàdúrà. Ó rí ibì kan tó pa rọ́rọ́ nínú ọgbà Gẹ́tísémánì. Ìgbà yẹn ló fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ní ìmọ̀ràn pàtàkì kan pé kí wọ́n máa gbàdúrà. Nígbà tí wọ́n fi máa dénú ọgbà Gẹ́tísémánì, ilẹ̀ ti ṣú gan-an, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀gànjọ́ òru. Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé ‘kí wọ́n máa ṣọ́nà,’ ó sì lọ gbàdúrà. (Mát. 26:37-39) Àmọ́ bí Jésù ṣe ń gbàdúrà, ṣe ni wọ́n sùn lọ. Nígbà tí Jésù rí i pé wọ́n ń sùn, ó tún rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ‘máa ṣọ́nà, kí wọ́n sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo.’ (Mát. 26:40, 41) Jésù mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ti ṣe wàhálà púpọ̀, ó sì ti rẹ̀ wọ́n, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé “ní tòótọ́, ẹ̀mí ń fẹ́, àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.” Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Jésù lọ gbàdúrà tó sì tún pa dà wá, àmọ́ nígbà tó dé, ó rí i pé wọ́n ń sùn dípò kí wọ́n máa gbàdúrà.—Mát. 26:42-45. w22.01 28 ¶10-11