December
Friday, December 1
Wọ́n á fetí sí ohùn mi.—Jòh. 10:16.
Jésù fi àjọṣe tó wà láàárín òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ wé àjọṣe tó máa ń wà láàárín olùṣọ́ àgùntàn kan àtàwọn àgùntàn ẹ̀. (Jòh. 10:14) Àfiwé yẹn bá a mu wẹ́kú torí pé àwọn àgùntàn máa ń dá ohùn olùṣọ́ wọn mọ̀, wọ́n sì máa ń fetí sí i. Ọkùnrin kan tó rìnrìn àjò afẹ́ rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ pé: “Nígbà témi àtàwọn tá a jọ rìnrìn àjò fẹ́ ya fọ́tò àwọn àgùntàn kan, a gbìyànjú láti bá wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè sún mọ́ wa. Àmọ́ wọn ò sún mọ́ wa torí pé wọn ò dá ohùn wa mọ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni ọmọkùnrin kan tó ń da àwọn àgùntàn náà dé. Bó ṣe ń pè wọ́n báyìí, ni wọ́n ń gbá tẹ̀ lé e.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin arìnrìn-àjò yẹn rán wa létí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Wọ́n á fetí sí ohùn mi.” Àmọ́ ọ̀run ni Jésù ń gbé. Torí náà, báwo la ṣe lè fetí sí ohùn rẹ̀? Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé à ń fetí sí ohùn Ọ̀gá wa ni pé ká máa fi àwọn ohun tó ń kọ́ wa ṣèwàhù.—Mát. 7:24, 25. w21.12 16 ¶1-2
Saturday, December 2
Gbogbo èèyàn ti ṣẹ̀, wọn ò sì kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.—Róòmù 3:23.
Nígbà kan, alágídí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó sì ṣenúnibíni tó burú gan-an sáwọn Kristẹni. Àmọ́ nígbà tó yá, ó gbà pé ohun tóun ṣe ò dáa, ó sì yí pa dà. (1 Tím. 1:12-16) Jèhófà ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́, ó wá di alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, tó ń fàánú hàn sí wọn, tó sì nírẹ̀lẹ̀. Ó mọ̀ pé Jèhófà ti dárí ji òun, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kó máa ronú ṣáá nípa àwọn àṣìṣe tó ti ṣe. (Róòmù 7:21-25) Ó mọ̀ pé òun kì í ṣe ẹni pípé. Torí náà, ó ṣiṣẹ́ kára kó lè túbọ̀ fìwà jọ Kristi, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa jẹ́ kóun ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun yanjú. (1 Kọ́r. 9:27; Fílí. 4:13) Kì í ṣe torí pé àwọn alàgbà jẹ́ ẹni pípé ni Jèhófà fi yàn wọ́n. Àmọ́ tí wọ́n bá ṣàṣìṣe, Jèhófà fẹ́ kí wọ́n gbà pé àwọn ṣàṣìṣe, kí wọ́n sì ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kí wọ́n lè túbọ̀ fìwà jọ Kristi. (Éfé. 4:23, 24) Ẹ̀yin alàgbà gbọ́dọ̀ máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ ara yín wò, kẹ́ ẹ lè ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa jẹ́ kẹ́ ẹ láyọ̀, ó sì máa jẹ́ kẹ́ ẹ ṣiṣẹ́ yín yanjú.—Jém. 1:25. w22.03 29-30 ¶13-15
Sunday, December 3
Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́.—Mát. 7:1.
Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí i pé a ti ń dá ẹnì kan tá a jọ ń sin Jèhófà lẹ́jọ́? Ó yẹ ká rántí ohun tí Bíbélì sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa. (Jém. 2:8) Bákan náà, ó yẹ ká gbàdúrà sí Jèhófà látọkàn wá, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká má dáni lẹ́jọ́ mọ́. Ó yẹ ká ṣiṣẹ́ lórí àdúrà tá a gbà, ká wá àyè láti wà pẹ̀lú ẹni náà ká lè túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́. A lè sọ fún un pé kó jẹ́ ká jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí ká pè é wá jẹun nílé wa. Bá a bá ṣe ń mọ ẹni náà sí i, tá a sì ń wo ibi tó dáa sí, ńṣe là ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àṣẹ olùṣọ́ àgùntàn rere tó sọ pé ká yéé dáni lẹ́jọ́. Bí àwọn àgùntàn ṣe máa ń fetí sí ohùn olùṣọ́ àgùntàn, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe máa ń fetí sí ohùn rẹ̀. Bóyá a wà lára “agbo kékeré” tàbí lára “àwọn àgùntàn mìíràn,” ẹ jẹ́ ká máa fetí sí ohùn olùṣọ́ àgùntàn rere, ká sì máa ṣègbọràn sí i.—Lúùkù 12:32; Jòh. 10:11, 14, 16. w21.12 19 ¶11; 21 ¶17-18
Monday, December 4
Ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbà ọkùnrin fún un.—1 Ọba 12:8.
Nígbà tí Rèhóbóámù di ọba Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn ẹ̀ sọ pé kó ṣe ohun kan fún àwọn. Wọ́n ní kó dín iṣẹ́ tí Sólómọ́nì bàbá ẹ̀ ní káwọn máa ṣe kù. Ni Rèhóbóámù bá lọ bá àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì pé kí wọ́n gba òun nímọ̀ràn nípa ohun tí òun máa sọ fáwọn èèyàn náà, ohun tó ṣe yẹn sì bọ́gbọ́n mu. Àwọn àgbààgbà yẹn sọ fún un pé tó bá ṣe ohun táwọn èèyàn náà fẹ́, wọ́n máa tì í lẹ́yìn. (1 Ọba 12:3-7) Ó hàn gbangba pé ìmọ̀ràn táwọn àgbààgbà yẹn gba Rèhóbóámù ò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Torí náà, ó lọ fọ̀rọ̀ lọ àwọn ojúgbà ẹ̀. Wọ́n ní ṣe ni kó fi kún iṣẹ́ táwọn èèyàn náà ń ṣe. (1 Ọba 12:9-11) Ó yẹ kí Rèhóbóámù bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà, kóun lè ṣèpinnu tó tọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn táwọn ojúgbà ẹ̀ gbà á ló fara mọ́. Ibi tọ́rọ̀ náà já sí fún Rèhóbóámù àtàwọn èèyàn Ísírẹ́lì ò dáa rárá. Bíi ti Rèhóbóámù, ìmọ̀ràn tí wọ́n máa fún wa lè má bá wa lára mu. Síbẹ̀, tó bá jẹ́ pé Bíbélì ni wọ́n fi gbà wá nímọ̀ràn, ó yẹ ká gba ìmọ̀ràn náà. w22.02 9 ¶6
Tuesday, December 5
Ògo àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn.—Òwe 20:29.
Ẹni tó bá nírẹ̀lẹ̀ tó sì mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa ń pọkàn pọ̀ sórí ohun táwọn ọ̀dọ́ lè ṣe dípò kó máa ronú nípa ohun tí wọn ò mọ̀. Bákan náà, kò ní máa wò wọ́n bíi pé wọ́n fẹ́ gbaṣẹ́ mọ́ òun lọ́wọ́, àmọ́ á kà wọ́n sí alábàáṣiṣẹ́ òun. Àwọn àgbàlagbà gbà pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọ̀dọ́ jẹ́, wọ́n sì mọyì ohun táwọn ọ̀dọ́ ń ṣe. Bí okun àwọn àgbàlagbà ṣe ń dín kù, inú wọn máa ń dùn pé àwọn ọ̀dọ́ tó lókun, tó sì múra tán láti ṣe iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí wà nínú ìjọ. Bíbélì sọ pé Náómì jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn àgbàlagbà. Ó gbà kí ẹni tí ò tó òun lọ́jọ́ orí ran òun lọ́wọ́, ó sì mọyì ìrànlọ́wọ́ náà. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Náómì kú, Náómì rọ Rúùtù tó jẹ́ ìyàwó ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀ pé kó pa dà sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀. Àmọ́ Rúùtù kọ̀, ó ní òun máa tẹ̀ lé Náómì pa dà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Náómì sì gbà kó ran òun lọ́wọ́. (Rúùtù 1:7, 8, 18) Ohun tí wọ́n ṣe yẹn ṣe àwọn méjèèjì láǹfààní! (Rúùtù 4:13-16) Àwọn àgbàlagbà tó bá nírẹ̀lẹ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Náómì. w21.09 10-11 ¶9-11
Wednesday, December 6
Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn. —Héb. 6:10.
Bàbá wa ọ̀run mọ ohun tí agbára ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbé. Ó ṣeé ṣe kó o mọ nǹkan kan ṣe ju àwọn èèyàn ẹ kan tó o mọ̀, tó o sì fẹ́ràn. Ó sì lè jẹ́ pé o ò lè ṣe tó àwọn míì bóyá torí ọjọ́ ogbó, àìlera àti bó o ṣe máa pèsè fún ìdílé ẹ. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má jẹ́ kó sú ẹ. (Gál. 6:4) Jèhófà ò ní gbàgbé iṣẹ́ tó o ṣe. Tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, tó o sì ń ṣe é tọkàntọkàn, inú Jèhófà máa dùn gan-an. Jèhófà mọ àwọn nǹkan tó wà lọ́kàn ẹ tó o fẹ́ ṣe. Torí náà, ó fẹ́ kí inú ẹ máa dùn bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ gbé nínú ìjọsìn rẹ̀. Ọkàn wa balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà máa ń ran àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ tá a bá wà nínú ìṣòro. (Àìsá. 41:9, 10) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe fún wa tó jẹ́ ká máa láyọ̀ bá a ṣe ń jọ́sìn ẹ̀. Torí náà, òun ló lẹ́tọ̀ọ́ “láti gba ògo àti ọlá”!—Ìfi. 4:11. w22.03 24 ¶16; 25 ¶18
Thursday, December 7
Mo yára, mi ò sì jáfara láti pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́. —Sm. 119:60.
A fẹ́ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Àmọ́, kò yẹ ká banú jẹ́ tá ò bá lè ṣe bí Jésù ti ṣe gẹ́lẹ́. (Jém. 3:2) Ẹnì kan tó ń kọ́ṣẹ́ lè má lè ṣe gbogbo nǹkan gẹ́lẹ́ lọ́nà tí ọ̀gá ẹ̀ ń gbà ṣe nǹkan. Àmọ́ bó ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe tó ṣe, tó sì ń ṣe gbogbo nǹkan tó lè ṣe láti mọ bí ọ̀gá ẹ̀ ṣe ń ṣe nǹkan, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, á máa mọṣẹ́ náà sí i. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń fi ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì sílò, tá a sì ń sapá láti sunwọ̀n sí i, á rọrùn fún wa láti túbọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (Sm. 119:59) Àwọn tó mọ tara wọn nìkan ló pọ̀ jù nínú ayé lónìí. Àmọ́ àwa èèyàn Jèhófà yàtọ̀ sí wọn. A ti kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù pé kò mọ tara ẹ̀ nìkan, tàwọn èèyàn ló máa ń gbọ́ ṣáájú tiẹ̀, a sì ti pinnu pé àá máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. (1 Pét. 2:21) Torí náà bíi ti Jésù, tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ dípò kó jẹ́ pé tara wa nìkan làá máa rò, àwa náà máa láyọ̀ torí a mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa. w22.02 24 ¶16; 25 ¶18
Friday, December 8
Àwọn nǹkan kan nínú wọn ṣòroó lóye. —2 Pét. 3:16.
Bíbélì wà lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà tọ́ àwa èèyàn ẹ̀ sọ́nà lónìí. Tá a bá ń ronú lórí ohun tí Jèhófà ń kọ́ wa, á rọrùn fún wa láti ṣe ohun tó ní ká ṣe, àá sì ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yanjú. (1 Tím. 4:15, 16) Jèhófà tún ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti tọ́ wa sọ́nà. (Mát. 24:45) Nígbà míì, ẹrú yìí máa ń fún wa láwọn ìtọ́ni kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ yé wa. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ní ká múra sílẹ̀ de àwọn àjálù kan tá a ronú pé kò lè ṣẹlẹ̀ lágbègbè wa láé. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá ronú pé ìtọ́ni tí wọ́n fún wa ò bọ́gbọ́n mu? A lè ronú nípa àwọn ẹlòmíì tá a kà nípa wọn nínú Bíbélì ti wọ́n gba àwọn ìtọ́ni kan tó jẹ́ pé lójú èèyàn, kò bọ́gbọ́n mu, àmọ́ àwọn ìtọ́ni yẹn gan-an ló gba ẹ̀mí wọn là.—Oníd. 7:7; 8:10. w22.03 18-19 ¶15-16
Saturday, December 9
Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.—Lúùkù 23:46.
Ìgbàgbọ́ tó lágbára tí Jésù ní nínú Jèhófà ló mú kó sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Jésù mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló lè jí òun dìde, ó sì dá a lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé òun. Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ? Ó yẹ kí ìwọ náà ṣe tán láti fi ẹ̀mí rẹ sọ́wọ́ Jèhófà. Kó o tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ “fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” (Òwe 3:5) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) kan tó ń jẹ́ Joshua nígbà tó ní àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí. Ó kọ̀ jálẹ̀ nígbà táwọn dókítà fẹ́ tọ́jú ẹ̀ lọ́nà tí kò bá ìlànà Bíbélì mu. Nígbà tó ku díẹ̀ kó kú, ó sọ fún màmá rẹ̀ pé: “Màámi, Jèhófà máa bójú tó mi. . . . Ó dá mi lójú pé kò ní fi mí sílẹ̀. Mo mọ̀ pé Jèhófà máa jí mi dìde. Ó rí ọkàn mi, ó sì mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ òun.” Torí náà, ó yẹ kí kálukú wa bi ara ẹ̀ pé, ‘Tí mo bá dojú kọ àdánwò tó lè gbẹ̀mí mi, ṣé màá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé kò ní gbàgbé mi, ó sì máa jí mi dìde?’ w21.04 12-13 ¶15-16
Sunday, December 10
Ẹni tó bá ń mára tu àwọn míì, ara máa tu òun náà. —Òwe 11:25.
Jèhófà máa ń tipasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù fún wa lókun. Tá a bá ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn míì, inú wa máa ń dùn, yálà wọ́n tẹ́tí sí wa àbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn kan máa ń ronú pé àwọn ò lè ṣe tó báwọn ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nítorí ipò tí wọ́n wà. Tó bá jẹ́ bó ṣe rí lára ẹ nìyẹn, rántí pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tágbára ẹ gbé. Jèhófà ń rí gbogbo ìsapá tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bá ò tiẹ̀ lè jáde nílé, ó sì mọyì ẹ̀. Ó lè fún wa láǹfààní láti wàásù fún àwọn tó ń tọ́jú wa. Tá a bá ń fi ohun tá à ń ṣe báyìí wé ohun tá a ti ṣe sẹ́yìn, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Àmọ́, tá a bá ń kíyè sí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ báyìí, àá lókun, àá sì máa láyọ̀ bá a ṣe ń fara da àwọn ìṣòro wa. Bá a ṣe ń fún irúgbìn òtítọ́, a ò mọ èyí tó máa hù táá sì ṣe dáadáa.—Oníw. 11:6. w21.05 24-25 ¶14-17
Monday, December 11
Kí ló dé tí o kò fi ka ọ̀rọ̀ Jèhófà sí, tí o wá ṣe ohun tó burú lójú rẹ̀?—2 Sám. 12:9.
Ojúkòkòrò mú kí Ọba Dáfídì gbàgbé gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe fún un. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà dá a lọ́lá, ó mú kó gbayì, ó sì mú kó ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. Kódà, Dáfídì fúnra ẹ̀ sọ pé àwọn ohun tí Jèhófà ṣe fún òun “pọ̀ ju ohun tí [òun] lè ròyìn!” (Sm. 40:5) Àmọ́ ìgbà kan wà tí Dáfídì gbàgbé àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ní ju ìyàwó kan lọ, ó jẹ́ kí ọkàn ẹ̀ fà sí ìyàwó oníyàwó. Bátí-ṣébà lorúkọ obìnrin náà, Ùráyà ọmọ Hétì sì lọkọ ẹ̀. Dáfídì bá obìnrin náà sùn, ó sì lóyún. Àfi bíi pé ìyẹn nìkan ò tó, Dáfídì tún ṣètò bí wọ́n ṣe pa ọkọ obìnrin náà! (2 Sám. 11:2-15) Ẹ gbọ́ ná, ṣé Dáfídì rò pé Jèhófà ò rí òun ni? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí Dáfídì ti ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà, ó ṣojúkòkòrò, ó sì jìyà ẹ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, Dáfídì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀, ó sì ronú pìwà dà. Ẹ wo bí inú ẹ̀ ṣe máa dùn tó pé Jèhófà dárí ji òun, ó sì fi ojúure hàn sóun!—2 Sám. 12:7-13. w21.06 17 ¶10
Tuesday, December 12
Kì í ṣe pé àwa fúnra wa kúnjú ìwọ̀n . . . , Ọlọ́run ló ń mú ká kúnjú ìwọ̀n.—2 Kọ́r. 3:5.
Ó lè máa ṣe wá bíi pé a ò ní lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A lè ronú pé òye wa ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ tó débi tá a fi máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe rí lára ẹ nìyẹn, jẹ́ ká wo àwọn nǹkan mẹ́ta táá jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìwọ náà lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àkọ́kọ́, Jèhófà mọ̀ pé o tóótun láti kọ́ àwọn míì. Ìkejì, Jésù tó ní “gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé” ló pàṣẹ pé kó o máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. (Mát. 28:18) Ìkẹta, àwọn míì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jésù bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, kó sì kọ́ òun ní ohun tí òun máa sọ, ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Jòh. 8:28; 12:49) Yàtọ̀ síyẹn, o lè ní kí alábòójútó àwùjọ rẹ, aṣáájú-ọ̀nà kan tàbí akéde kan tó nírìírí ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀kan lára ohun táá jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé kó o bá wọn ṣiṣẹ́ kó o sì kíyè sí bí wọ́n ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. w21.07 6 ¶12
Wednesday, December 13
Ẹni tó bá jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tó kéré jù jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tó pọ̀ pẹ̀lú, ẹni tó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tó kéré jù jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tó pọ̀ pẹ̀lú. —Lúùkù 16:10.
Bí òpin ayé burúkú yìí ṣe ń sún mọ́lé, ó yẹ ká fọkàn tán Jèhófà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé ohun tó tọ́ ló máa ń ṣe. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀? Nígbà ìpọ́njú ńlá, ètò Ọlọ́run lè ní ká ṣe ohun kan tó jọ pé kò bọ́gbọ́n mu tàbí tí kò yé wa. A mọ̀ pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ò ní bá wa sọ̀rọ̀. Ó lè jẹ́ àwọn tó ń ṣàbójútó ètò rẹ̀ ló máa lò láti bá wa sọ̀rọ̀. Ìgbà yẹn kọ́ ló yẹ ká máa ṣiyèméjì pé ṣóhun tí wọ́n sọ fún wa jóòótọ́ tàbí ká máa rò pé, ‘Ṣé Jèhófà ló sọ bẹ́ẹ̀ ni àbí èrò tiwọn ni wọ́n sọ fún wa?’ Ṣé o máa fọkàn tán Jèhófà àti ètò rẹ̀ lákòókò tí nǹkan bá nira yẹn? Irú ojú tó o fi ń wo ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ fún wa ní báyìí máa fi hàn bóyá wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà yẹn. Tó o bá ń tẹ̀ lé ohun tí wọ́n ń sọ fún wa báyìí, tó o sì ń ṣègbọràn, wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá. w22.02 6 ¶15
Thursday, December 14
Ṣé ohun tí mo ṣe wá tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiyín?—Oníd. 8:2.
Jèhófà mú kí Gídíónì àtàwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọmọ ogun rẹ̀ ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá lọ́nà tó kàmàmà, ìyẹn sì lè mú kí wọ́n gbéra ga. Nígbà táwọn ọkùnrin Éfúrémù lọ bá Gídíónì, dípò kí wọ́n gbóríyìn fún un, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá a fa wàhálà torí pé kò pè wọ́n nígbà tó fẹ́ lọ jà. (Oníd. 8:1) Gídíónì rán wọn létí bí Jèhófà ṣe lò wọ́n láti gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe. Ohun tí Gídíónì sọ yìí mú kí “ara wọn balẹ̀.” (Oníd. 8:3) Dípò kí Gídíónì bínú, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí àlàáfíà lè wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Látinú ohun táwọn ọmọ Éfúrémù ṣe, a kẹ́kọ̀ọ́ pé bá a ṣe máa gbé orúkọ Jèhófà ga ló yẹ kó jẹ wá lógún, kì í ṣe bá a ṣe máa gbayì lójú àwọn míì. Àwọn olórí ìdílé àtàwọn alàgbà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Gídíónì. Tẹ́nì kan bá bínú sí wa, dípò tá a fi máa bínú, ṣe ló yẹ ká gbìyànjú láti lóye ẹni yẹn. Kódà, a lè kíyè sí àwọn nǹkan dáadáa tónítọ̀hún ṣe, ká sì gbóríyìn fún un. Ìrẹ̀lẹ̀ ló máa jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, bí àlàáfíà ṣe máa jọba ṣe pàtàkì ju iyì ara ẹni lọ. w21.07 16-17 ¶10-12
Friday, December 15
Jẹ́ ká dá èèyàn ní àwòrán wa.—Jẹ́n. 1:26.
Jèhófà dá wa lọ́lá ní ti pé ó dá wa ní àwòrán rẹ̀. Torí pé a jẹ́ àwòrán Ọlọ́run, a lè fìwà jọ ọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè fìfẹ́ hàn, a lè ṣàánú, a lè jẹ́ adúróṣinṣin, a sì lè jẹ́ olódodo. (Sm. 86:15; 145:17) Bá a ṣe túbọ̀ ń fìwà jọ Jèhófà, ṣe là ń bọlá fún un, tá a sì ń jẹ́ kó mọ̀ pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa. (1 Pét. 1:14-16) Bákan náà, tá a bá fìwà jọ Jèhófà, inú wa á dùn, àá sì di ọ̀kan lára irú àwọn tó fẹ́ nínú ìdílé rẹ̀. Jèhófà dá ayé lọ́nà tó fi máa dùn ún gbé. Kí Jèhófà tó dá Ádámù, ó ti ṣètò gbogbo ohun táwa èèyàn máa nílò sínú ayé. (Jóòbù 38:4-6; Jer. 10:12) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì lawọ́, ó pèsè gbogbo ohun táá mú ká gbádùn ìgbésí ayé wa. (Sm. 104:14, 15, 24) Bí Jèhófà ṣe ń dá àwọn nǹkan, bẹ́ẹ̀ náà ló ń yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì “rí i pé ó dára.”—Jẹ́n. 1:10, 12, 31. w21.08 3 ¶5-6
Saturday, December 16
Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu. —Gál. 5:22, 23.
Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ máa wàásù ká sì máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20; Róòmù 10:14) Ṣé wàá fẹ́ túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ pàtàkì yìí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè fi ṣe àfojúsùn ẹ láti ka àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé Kíkọ́ni, kó o sì fi àwọn àbá inú ẹ̀ sílò. Fi sọ́kàn pé ọ̀kan lára àwọn àfojúsùn tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ kó o ní ni pé kó o túbọ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí kó o lè máa múnú Jèhófà dùn. (Kól. 3:12; 2 Pét. 1:5-8) Ó dájú pé gbogbo wa ló wù ká ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà ju ohun tá à ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Nínú ayé tuntun, gbogbo wa pátápátá la máa lè sin Jèhófà dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Àmọ́ ní báyìí tá a bá ń fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ojúṣe tá a ní nínú ìjọsìn Jèhófà, àá láyọ̀, a ò sì ní rẹ̀wẹ̀sì. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àá mú ìyìn àti ògo bá Jèhófà “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tím. 1:11) Torí náà, jẹ́ kí iṣẹ́ ìsìn tó ò ń ṣe báyìí máa múnú ẹ dùn! w21.08 25 ¶18-20
Sunday, December 17
Ẹnikẹ́ni tó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà.—Héb. 11:6.
Tó bá jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí ẹ, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti kọ́ ẹ nípa Jèhófà láti kékeré. Wọ́n kọ́ ẹ pé òun ni Ẹlẹ́dàá, pé ó láwọn ànímọ́ tó dáa àti pé ó máa sọ ayé di Párádísè. (Jẹ́n. 1:1; Ìṣe 17:24-27) Ọ̀pọ̀ èèyàn ò gbà pé Ọlọ́run wà débi tí wọ́n á fi gbà pé òun ló dá gbogbo nǹkan. Wọ́n gbà pé ṣe ni gbogbo nǹkan ṣàdédé wà àti pé ara àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí kéékèèké làwọn ẹranko àtàwa èèyàn ti wá. Ó yani lẹ́nu pé àwọn kan tó gba ẹ̀kọ́ yìí gbọ́ kàwé dáadáa. Wọ́n lè sọ pé sáyẹ́ǹsì ti fi hàn pé ohun tó wà nínú Bíbélì kì í ṣe òótọ́ àti pé àwọn aláìmọ̀kan àtàwọn tí ò lajú ló gbà pé Ẹlẹ́dàá wà. Láìka bó ti pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà, gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, “ọgbọ́n orí àti ìtànjẹ lásán” táwọn èèyàn ń gbé lárugẹ ò ní ṣì wá lọ́nà.—Kól. 2:8. w21.08 14 ¶1-3
Monday, December 18
Jèhófà, Ọlọ́run wa, ìwọ ló tọ́ sí láti gba ògo àti ọlá àti agbára.—Ìfi. 4:11.
Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ bí Ébẹ́lì, Nóà, Ábúráhámù àti Jóòbù fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, àwọn sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí wọ́n ṣe fi hàn ni pé wọ́n ṣègbọràn sí Jèhófà, wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹ̀, wọ́n sì rúbọ sí i. Gbogbo nǹkan tí wọ́n lè ṣe láti bọlá fún Jèhófà ni wọ́n ṣe, Jèhófà sì tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn. Nígbà tó yá, Jèhófà fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ní Òfin Mósè. Àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa ṣe nínú ìjọsìn òun ló wà nínú òfin yẹn. Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jésù, Jèhófà ò fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ òun tẹ̀ lé Òfin Mósè mọ́. (Róòmù 10:4) Òfin tuntun, ìyẹn “òfin Kristi” ló fẹ́ káwọn Kristẹni máa tẹ̀ lé. (Gál. 6:2) Jèhófà ò fẹ́ kí wọ́n máa tẹ̀ lé òfin ṣe-tibí-má-ṣe-tọ̀hún. Ohun tó fẹ́ ni pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù àtohun tó fi ń kọ́ni. Bákan náà lónìí, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi. Ohun táà ń ṣe yìí ń múnú Jèhófà dùn, ó sì ń ‘mára tù’ wá.—Mát. 11:29. w22.03 20-21 ¶4-5
Tuesday, December 19
Ó sábà máa ń lọ sí àwọn ibi tó dá láti gbàdúrà.—Lúùkù 5:16.
Jèhófà máa ń fetí sí àwọn ọmọ rẹ̀. Ó dáhùn àwọn àdúrà tí Jésù gbà nígbà tó wà láyé. Jésù máa ń gbàdúrà kó tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, Jèhófà sì gbọ́ àdúrà ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó gbàdúrà sí Jèhófà nígbà tó fẹ́ yan àwọn àpọ́sítélì méjìlá. (Lúùkù 6:12, 13) Jèhófà tún gbọ́ àdúrà tí Jésù gbà nígbà tó ní ìdààmú ọkàn. Kí Júdásì tó da Jésù, Jésù gbàdúrà gan-an sí Bàbá rẹ̀ nípa àwọn àdánwò líle koko tó máa tó dojú kọ. Kì í ṣe pé Jèhófà gbọ́ àdúrà Jésù nìkan, ó tún rán áńgẹ́lì kan láti fún un lókun. (Lúùkù 22:41-44) Lónìí, Jèhófà ṣì máa ń gbọ́ àdúrà àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lásìkò tó tọ́ àti lọ́nà tó dáa jù lọ. (Sm. 116:1, 2) Ẹ jẹ́ ká wo bí arábìnrin kan ní Íńdíà ṣe rí ọ̀nà tí Jèhófà gbà dáhùn àdúrà ẹ̀. Ó ní ìdààmú ọkàn tó lékenkà, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà gan-an nípa ẹ̀. Ó sọ pé: “Ètò JW Broadcasting® ti May 2019 tó sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè borí àníyàn àti ìdààmú ọkàn bọ́ sásìkò gẹ́lẹ́ fún mi. Ṣe ni Jèhófà fi ètò yẹn dáhùn àdúrà mi.” w21.09 21-22 ¶6-7
Wednesday, December 20
[Ẹ] sá lọ sí àwọn òkè. —Lúùkù 21:21.
Wo bí nǹkan ṣe máa rí fáwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ yẹn lẹ́yìn tí wọ́n filé fọ̀nà wọn sílẹ̀ lọ sílùú míì. Ṣé o rò pé ó máa rọrùn? Kò sí àní-àní pé ó gba ìgbàgbọ́ torí ó gbọ́dọ̀ dá wọn lójú pé Jèhófà máa pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn. Bó ti wù kó rí, ohun kan wà tó mú kíyẹn ṣeé ṣe. Kí ni nǹkan náà? Lọ́dún márùn-ún ṣáájú ìgbà táwọn ọmọ ogun Róòmù yí Jerúsálẹ́mù ká, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù yẹn nímọ̀ràn tó máa ṣe wọ́n láǹfààní, ó ní: “Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín, bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn. Torí ó ti sọ pé: ‘Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.’ Ká lè nígboyà gidigidi, ká sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?’ ” (Héb. 13:5, 6) Ẹ wo bí nǹkan ṣe máa rọrùn tó fáwọn tó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù kó tó di pé àwọn ọmọ ogun Róòmù dé. Ìyẹn ni ò jẹ́ kó nira fún wọn láti ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun tí wọ́n ní níbi tuntun tí wọ́n lọ. Wọn ò ṣiyèméjì pé Jèhófà máa bójú tó àwọn. w22.01 4 ¶7, 9
Thursday, December 21
Àánú [Jèhófà] wà lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.—Sm. 145:9.
Tí wọ́n bá pe ẹnì kan ní aláàánú, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó máa wá sí wa lọ́kàn ni ẹnì kan tó jẹ́ onínúure, tó tutù, tára ẹ̀ balẹ̀, tó sì lawọ́. Ó tún ṣeé ṣe kí ìtàn tí Jésù sọ nípa aláàánú ará Samáríà wá sí wa lọ́kàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin náà kì í ṣe Júù, ó “ṣàánú” Júù kan táwọn olè ṣe léṣe. “Àánú [Júù náà] ṣe” ará Samáríà yẹn, ó sì ṣètò bí wọ́n ṣe máa tọ́jú rẹ̀. (Lúùkù 10:29-37) Ìtàn yìí kọ́ wa pé àánú jẹ́ ọ̀kan lára ànímọ́ Ọlọ́run tó fani mọ́ra. Ọlọ́run máa ń ṣàánú wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ojoojúmọ́ la sì máa ń rọ́wọ́ àánú Ọlọ́run láyé wa. Ọ̀nà míì tún wà tá a lè gbà fàánú hàn. Ẹni tó jẹ́ aláàánú lè pinnu pé òun ò ní fìyà jẹ ẹnì kan tó yẹ kó jìyà ohun tó ṣe. Jèhófà máa ń fàánú hàn sí wa lọ́nà yẹn. Onísáàmù náà sọ pé: “Kò fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa hùwà sí wa.” (Sm. 103:10) Àmọ́ láwọn ìgbà míì, Jèhófà máa ń fún ẹni tó bá ṣẹ̀ ní ìbáwí tó yẹ. w21.10 8 ¶1-2
Friday, December 22
Ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ ò ní kúrò lọ́dọ̀ rẹ.—Àìsá. 54:10.
Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ nìkan ló máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí. Ohun tí Ọba Dáfídì àti wòlíì Dáníẹ́lì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ pé: “Máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn nìṣó sí àwọn tó mọ̀ ọ́.” “Ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wà títí ayé sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.” Dáníẹ́lì ní tiẹ̀ sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, [ẹni tó] ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (Sm. 36:10; 103:17; Dán. 9:4) Bí àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ, ìdí tí Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Torí náà, àwọn tó bá ń jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tọ́ nìkan ló máa ń fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí. Kó tó di pé a di ìránṣẹ́ Jèhófà la ti ń gbádùn ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí aráyé. (Sm. 104:14) Àmọ́, lẹ́yìn tá a di ìránṣẹ́ rẹ̀, a wá ń gbádùn ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. w21.11 4 ¶8-9
Saturday, December 23
Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn.—Mát. 4:10.
Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, a ti pinnu pé ọ̀rọ̀ Jésù la máa tẹ̀ lé. Lónìí, ọ̀pọ̀ fẹ́ràn láti máa tẹ̀ lé àwọn olórí ẹ̀sìn tó lókìkí. Wọ́n fẹ́ràn wọn débi pé wọ́n ti sọ wọ́n dòrìṣà. Àwọn èèyàn máa ń rọ́ lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì wọn, wọ́n máa ń ra ìwé wọn, wọ́n sì máa ń dáwó rẹpẹtẹ fáwọn olórí ẹ̀sìn náà àti ṣọ́ọ̀ṣì wọn. Gbogbo nǹkan táwọn olórí ẹ̀sìn yẹn bá sọ làwọn kan lára ọmọ ìjọ wọn máa ń ṣe. Kódà, bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn olórí ẹ̀sìn wọn gẹ̀gẹ̀, wọn ò lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fún Jésù tí wọ́n bá rí i lójúkojú! Àmọ́, àwa tá à ń fi òótọ́ jọ́sìn Jèhófà ò fi èèyàn kankan ṣe olórí wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní àwọn tó ń ṣe àbójútó wa nínú ètò Ọlọ́run, tá a sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn, a máa ń fi ọ̀rọ̀ Jésù yìí sọ́kàn pé: ‘Arákùnrin ni gbogbo yín.’ (Mát. 23:8-10) A kì í jọ́sìn ẹnikẹ́ni bóyá olórí ẹ̀sìn lẹni náà tàbí olóṣèlú, a kì í sì í ti ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe lẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ náà la kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí àwọn nǹkan míì tó ń lọ nínú ayé. Àwọn nǹkan yìí mú ká yàtọ̀ pátápátá sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn tó pe ara wọn ní Kristẹni.—Jòh. 18:36. w21.10 20 ¶6-7
Sunday, December 24
Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ . . . O ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.—Ẹ́kís. 20:2, 3.
Kristẹni kọ̀ọ̀kan tó bá fẹ́ jẹ́ mímọ́ gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òun ò jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe àárín òun àti Ọlọ́run jẹ́. Torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, a ti pinnu pé àá máa yẹra fún ìwà èyíkéyìí tó lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ Ọlọ́run. (Léf. 19:12; Àìsá. 57:15) Ọ̀nà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà ń fi hàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run àwọn ni pé wọ́n ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Léfítíkù 18:4 sọ pé: “Kí ẹ máa tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi, kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí ẹ sì máa rìn nínú wọn. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.” Léfítíkù orí 19 sọ lára “àwọn àṣẹ” náà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, ẹsẹ 5-8, 21 àti 22 sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń fi ẹran rúbọ. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ rú ẹbọ náà lọ́nà tí ò ní “sọ ohun mímọ́ Jèhófà di aláìmọ́.” Tá a bá ń ka àwọn ẹsẹ yìí, wọ́n á mú kó wù wá láti máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ká sì máa rú ẹbọ ìyìn sí i lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà bí Hébérù 13:15 ṣe gbà wá nímọ̀ràn. w21.12 5-6 ¶14-15
Monday, December 25
Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ.—Òwe 5:18.
Àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó máa jàǹfààní gan-an látinú ìrírí àwọn èèyàn tó gbára lé Jèhófà. Àwọn tọkọtaya kan ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Torí náà, o ò ṣe sún mọ́ wọn, kó o sì ní kí wọ́n gbà ẹ́ nímọ̀ràn nípa ohun tó o lè fayé ẹ ṣe? Ohun tó o lè ṣe nìyẹn táá fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Òwe 22:17, 19) Ẹ rántí pé, ẹ̀bùn àtàtà ni ìgbéyàwó jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Mát. 19:5, 6) Ó sì fẹ́ káwọn tọkọtaya gbádùn ẹ̀bùn náà gan-an. Ẹ̀yin tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, ẹ ò ṣe wò ó bóyá ohun tó yẹ kẹ́ ẹ fìgbésí ayé yín ṣe lẹ̀ ń ṣe báyìí? Ṣé ẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe láti fi hàn pé ẹ mọrírì ẹ̀bùn pàtàkì tí Jèhófà fún yín? Torí náà, ẹ máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà. Ẹ máa ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kẹ́ ẹ lè rí àwọn ìlànà tó bá ipò yín mu. Lẹ́yìn náà, ẹ rí i pé ẹ̀ ń fi àwọn ìmọ̀ràn tẹ́ ẹ rí níbẹ̀ sílò. Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ẹ máa láyọ̀, Jèhófà sì máa bù kún yín bẹ́ ẹ ṣe ń fi kún ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀! w21.11 19 ¶16, 18
Tuesday, December 26
Gbogbo wa ni a máa ń ṣàṣìṣe lọ́pọ̀ ìgbà.—Jém. 3:2, àlàyé ìsàlẹ̀.
Jémíìsì kò ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Jémíìsì kò rò pé ìdílé tí òun ti wá tàbí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tóun ní mú kóun di èèyàn pàtàkì tàbí kó dọ̀gá lórí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin inú ìjọ. Ó pe àwọn tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run ní “ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n.” (Jém. 1:16, 19; 2:5) Kò jẹ́ káwọn èèyàn máa rò pé ẹni pípé lòun. Ohun tá a rí kọ́: Ká máa rántí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa. A ò gbọ́dọ̀ máa rò pé lọ́nà kan, a sàn ju àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Tá a bá jẹ́ kí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rò pé a ò lè ṣàṣìṣe, wọ́n lè rò pé àwọn ò ní lè ṣègbọràn sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì á sì bá wọn. Àmọ́ tá a bá fòótọ́ inú sọ fún wọn pé kò rọrùn fáwa náà láti máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, tá a sì ṣàlàyé fún wọn bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro wa, ìyẹn á ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á sì rí i pé àwọn náà lè sin Jèhófà. w22.01 11-12 ¶13-14
Wednesday, December 27
Ẹ ní èrò yìí nínú yín, irú èyí tí Kristi Jésù náà ní.—Fílí. 2:5.
Tá a bá ń ronú bíi ti Jésù, àá máa ṣe nǹkan lọ́nà tó ń gbà ṣe nǹkan, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ máa fìwà jọ ọ́. (Héb. 1:3) Ẹnì kan lè sọ pé: ‘Ẹni pípé ni Jésù, kò sí bí mo ṣe lè fìwà jọ ọ́ délẹ̀délẹ̀!’ Tó bá jẹ́ pé ohun tó ò ń rò nìyẹn, fi àwọn nǹkan yìí sọ́kàn. Àkọ́kọ́, Jèhófà dá wa lọ́nà tá a lè fìwà jọ òun àti Jésù. Torí náà, a lè fìwà jọ wọ́n dé àyè kan. (Jẹ́n. 1:26) Ìkejì, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tó lágbára jù lọ láyé àti lọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tá ò lérò pé a lè ṣe. Ìkẹta, Jèhófà ò retí pé ká fìwà jọ òun délẹ̀délẹ̀ ní báyìí. Kódà, Bàbá wa tó nífẹ̀ẹ́ wa ti ṣètò ẹgbẹ̀rún ọdún kan (1,000) fún àwọn tó nírètí láti gbé ayé, kí wọ́n lè di ẹni pípé. (Ìfi. 20:1-3) Torí náà, ohun tí Jèhófà ń fẹ́ báyìí ni pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó máa ràn wá lọ́wọ́. w22.03 9 ¶5-6
Thursday, December 28
Kí n tó sọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu, wò ó, Jèhófà, o ti mọ gbogbo ohun tí mo fẹ́ sọ.—Sm. 139:4.
Àdúrà nìkan kọ́ lohun tó ń jẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ àwa àti Jèhófà lágbára. Àwọn nǹkan míì tó máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì máa wá sípàdé déédéé. Kí lo lè ṣe tí wàá fi lo àkókò tó o fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtèyí tó o fi wà nípàdé lọ́nà tó dáa? Bi ara ẹ pé ‘Àwọn nǹkan wo ló máa ń pín ọkàn mi níyà ti mo bá wà nípàdé àti nígbà tí mo bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?’ Ṣé kì í ṣe pé àwọn èèyàn máa ń pè mí tí wọ́n sì máa ń fi lẹ́tà àti ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù mi tàbí sórí ẹ̀rọ ìgbàlódé míì tí mo ní? Tó o bá rí i pé ọkàn ẹ ń rìn gbéregbère nígbà tóò ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí nígbà tó o wà nípàdé, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè pọkàn pọ̀. Ó lè má rọrùn fún ẹ láti pọkàn pọ̀ nígbà tó o bá ń jọ́sìn Ọlọ́run. Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn ẹ níyà. Torí náà, gbàdúrà pé kí àlàáfíà Ọlọ́run máa ṣọ́ ọkàn àti “agbára ìrònú” rẹ.—Fílí. 4:6, 7. w22.01 29-30 ¶12-14
Friday, December 29
Fetí sílẹ̀ kí o sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n.—Òwe 22:17.
Ọba Ùsáyà ò gba ìmọ̀ràn. Ó wọ ibì kan nínú tẹ́ńpìlì tó jẹ́ pé àwọn àlùfáà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti wọ ibẹ̀, ó sì fẹ́ sun tùràrí níbẹ̀. Àwọn àlùfáà Jèhófà sọ fún un pé: “Ùsáyà, kò tọ́ sí ọ láti sun tùràrí sí Jèhófà! Àwọn àlùfáà nìkan ló yẹ kó máa sun tùràrí.” Kí ni Ùsáyà wá ṣe? Ká ní ó gba ìmọ̀ràn yẹn tó sì kúrò nínú tẹ́ńpìlì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bóyá Jèhófà ò bá dárí jì í. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni “inú bí Ùsáyà.” Kí nìdí tí kò fi gba ìmọ̀ràn táwọn àlùfáà yẹn fún un? Ó gbà pé torí pé ọba ni òun, òun lè ṣe ohunkóhun tí òun bá fẹ́. Àmọ́ Jèhófà ò fara mọ́ irú èrò yẹn. Torí pé Ùsáyà ṣe ohun tí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe, Jèhófà fi ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú, ó sì “ya adẹ́tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.” (2 Kíró. 26:16-21) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ùsáyà kọ́ wa pé ẹni yòówù ká jẹ́, tá a bá kọ ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa látinú Bíbélì, a ò ní rí ojúure Jèhófà. w22.02 9 ¶7
Saturday, December 30
Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí pa dà, kí Ọlọ́run lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àwọn àsìkò ìtura lè wá látọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.—Ìṣe 3:19.
Ẹni tó ń hu “ìwà àtijọ́” kì í ronú lọ́nà tó tọ́, ó sì máa ń dẹ́ṣẹ̀. (Kól. 3:9) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń mọ tara ẹ̀ nìkan, ó tètè máa ń bínú, kì í moore, ó sì máa ń gbéra ga. Ó máa ń wo fíìmù ìṣekúṣe àti ti ìwà ipá. Lóòótọ́ ó ní àwọn ìwà kan tó dáa, ó sì máa ń kábàámọ̀ ohun búburú tó bá ṣe tàbí èyí tó sọ. Àmọ́ ó ṣòro fún un láti yí èrò àti ìwà rẹ̀ tí kò dáa pa dà. (Gál. 5:19-21; 2 Tím. 3:2-5) Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, kò sí ìkankan nínú wa tó lè mú gbogbo èrò burúkú kúrò lọ́kàn ẹ̀ pátápátá. Nígbà míì, a máa ń sọ tàbí ṣe àwọn nǹkan tá a máa pa dà kábàámọ̀ ẹ̀. (Jer. 17:9; Jém. 3:2) Tá a bá ti bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, a ò ní hùwà burúkú mọ́, ìwà wa á sì dáa.—Àìsá. 55:7. w22.03 3 ¶4-5
Sunday, December 31
Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.—Fílí. 2:3.
Ẹ̀yin alàgbà, ibi táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ yín dáa sí ni kẹ́ ẹ máa wò. Aláìpé ni wọ́n, síbẹ̀ gbogbo wọn ló ní ẹ̀bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Òótọ́ ni pé látìgbàdégbà, ó lè gba pé káwọn alàgbà máa tún èrò àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan ṣe. Àmọ́ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí ò dáa táwọn ará sọ tàbí ohun tó kù díẹ̀ káàtó tí wọ́n ṣe ló yẹ káwọn alàgbà máa wò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n máa wò ni ìfẹ́ tẹ́ni náà ní fún Jèhófà, bó ṣe ń fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ àti pé ó ṣì máa ṣe dáadáa lọ́jọ́ iwájú. Táwọn alàgbà bá ń wo ibi táwọn ará dáa sí, ìyẹn máa jẹ́ kára tu gbogbo àwọn ará tó wà nínú ìjọ. Ẹ máa fi sọ́kàn pé Jèhófà ò retí pé kẹ́ ẹ jẹ́ ẹni pípé, ohun tó fẹ́ ni pé kẹ́ ẹ jẹ́ olóòótọ́. (1 Kọ́r. 4:2) Ó dájú pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tóò ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Torí náà ẹ̀yin alàgbà, Jèhófà ò ní “gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀ bí ẹ ṣe ń ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, tí ẹ sì ń bá a lọ láti ṣe ìránṣẹ́.”—Héb. 6:10. w22.03 31 ¶19, 21