ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es24 ojú ìwé 7-17
  • January

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • January
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Monday, January 1
  • Tuesday, January 2
  • Wednesday, January 3
  • Thursday, January 4
  • Friday, January 5
  • Saturday, January 6
  • Sunday, January 7
  • Monday, January 8
  • Tuesday, January 9
  • Wednesday, January 10
  • Thursday, January 11
  • Friday, January 12
  • Saturday, January 13
  • Sunday, January 14
  • Monday, January 15
  • Tuesday, January 16
  • Wednesday, January 17
  • Thursday, January 18
  • Friday, January 19
  • Saturday, January 20
  • Sunday, January 21
  • Monday, January 22
  • Tuesday, January 23
  • Wednesday, January 24
  • Thursday, January 25
  • Friday, January 26
  • Saturday, January 27
  • Sunday, January 28
  • Monday, January 29
  • Tuesday, January 30
  • Wednesday, January 31
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
es24 ojú ìwé 7-17

January

Monday, January 1

Mo . . . rán Tímótì sí yín, torí ó jẹ́ ọmọ mi ọ̀wọ́n àti olóòótọ́ nínú Olúwa.—1 Kọ́r. 4:17.

Kí ló jẹ́ kí Tímótì wúlò fún Jèhófà? Ohun tó jẹ́ kó wúlò ni pé ó máa ń hùwà tó yẹ Kristẹni gan-an. (Fílí. 2:​19-22) Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa Tímótì jẹ́ ká mọ̀ pé Tímótì nírẹ̀lẹ̀, olóòótọ́ ni, ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, ó sì ṣeé fọkàn tán. Ó tún máa ń bójú tó àwọn ará. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi nífẹ̀ẹ́ Tímótì, tó sì gbé àwọn iṣẹ́ tí ò rọrùn láti bójú tó nínú ìjọ fún un. Lọ́nà kan náà, táwa náà bá ń hùwà tínú Jèhófà dùn sí, ó máa túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wa, àá sì wúlò gan-an nínú ìjọ. (Sm. 25:9; 138:6) Torí náà, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o mọ àwọn ìwà tó yẹ kó o ṣàtúnṣe ẹ̀. Lẹ́yìn náà, mú ìwà kan tó o máa ṣiṣẹ́ lé. O lè pinnu pé wàá túbọ̀ máa gba tàwọn ará rò. Yàtọ̀ síyẹn, o lè pinnu pé wàá túbọ̀ jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín ìwọ àtàwọn ará, wàá sì túbọ̀ máa dárí jì wọ́n. O lè ní kí ọ̀rẹ́ ẹ kan sọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe táá jẹ́ kí ìwà ẹ dáa sí i.—Òwe 27:6. w22.04 23 ¶4-5

Tuesday, January 2

Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò.—Gál. 6:4.

Jèhófà fẹ́ ká máa láyọ̀. Ohun tó sì jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé ayọ̀ jẹ́ apá kan èso tẹ̀mí tí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní. (Gál. 5:22) Torí pé ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ, ayọ̀ wa máa ń pọ̀ sí i tá a bá ń wàásù déédéé, tá a sì ń ran àwọn ará wa lọ́wọ́ lónírúurú ọ̀nà. (Ìṣe 20:35) Nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nǹkan méjì táá jẹ́ ká máa láyọ̀ nìṣó. Ohun àkọ́kọ́ tó sọ ni pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe fún Jèhófà. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, a máa láyọ̀. (Mát. 22:​36-38) Ohun kejì ni pé a ò gbọ́dọ̀ máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì. Ibi tí ìlera wa, àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a ti gbà àtàwọn ẹ̀bùn tá a ní bá lè jẹ́ ká ṣiṣẹ́ ìsìn wa dé, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Àmọ́ tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan lè ṣe jù wá lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ṣe ló yẹ kí inú wa máa dùn pé wọ́n ń lo ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wọn láti máa yìn ín. w22.04 10 ¶1-2

Wednesday, January 3

Ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.—Lúùkù 21:28.

Lójijì, àwọn orílẹ̀-èdè máa pa ìsìn èké run, ìparun ẹ̀ sì máa ya gbogbo ayé lẹ́nu. (Ìfi. 18:​8-10) Nígbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run, gbogbo aráyé máa mọ̀ ọ́n lára, nǹkan sì lè nira fáwọn èèyàn, àmọ́ inú àwa èèyàn Ọlọ́run máa dùn nígbà yẹn. Ó kéré tán, ohun méjì lá jẹ́ kínú wa máa dùn. Àkọ́kọ́, ìsìn èké tó jẹ́ ọ̀tá Jèhófà Ọlọ́run tipẹ́tipẹ́ ti pa run ráúráú. Ìkejì sì ni pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Ọlọ́run máa gbà wá lọ́wọ́ ayé burúkú yìí! Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé ‘ìmọ̀ tòótọ́ máa pọ̀ gan-an.’ Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lónìí nìyẹn! A ti lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó dá lórí àkókò tá à ń gbé yìí. (Dán. 12:​4, 9, 10) Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ láìkù síbì kan ń jẹ́ ká túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún Jèhófà àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Àìsá. 46:10; 55:11) Torí náà, tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, tó o sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ lágbára. Ó máa dáàbò bo àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e, ó sì máa fún wọn ní “àlàáfíà tí kò lópin.”—Àìsá. 26:3. w22.07 6-7 ¶16-17

Thursday, January 4

Wọ́n . . . kó wọn jọ sí ibi tí wọ́n ń pè ní Amágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.—Ìfi. 16:16.

Ìwé Ìfihàn sọ pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso lọ́run, wọ́n sì ti lé Sátánì kúrò lọ́run. (Ìfi. 12:​1-9) Àlàáfíà dé bá àwọn tó wà lọ́run nígbà tí wọ́n lé Sátánì kúrò níbẹ̀, àmọ́ ìyẹn dá wàhálà sílẹ̀ fún aráyé. Kí nìdí? Ìdí ni pé Sátánì ń gbéjà ko àwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn láyé. (Ìfi. 12:​12, 15, 17) Kí ló máa mú ká jẹ́ olóòótọ́ bí Sátánì tiẹ̀ ń gbéjà kò wá? (Ìfi. 13:10) Ohun tó máa jẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ ni pé ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ nínú ìwé Ìfihàn, àpọ́sítélì Jòhánù sọ díẹ̀ lára àwọn ohun rere tá a máa gbádùn láìpẹ́. Ọ̀kan lára ohun rere náà ni pé Ọlọ́run máa pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run. Ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìfihàn sọ fún wa pé “àwọn àmì” ni wọ́n máa fi ṣàlàyé àwọn ohun tá a máa kà nínú ìwé náà. Ìyẹn ni pé èdè àpèjúwe ni wọ́n máa lò.—Ìfi. 1:1. w22.05 8 ¶1-3

Friday, January 5

Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, èmi yóò mú kí o wá gbéjà ko ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀-èdè lè mọ̀ mí, kí wọ́n sì mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni mí nígbà tí wọ́n bá rí ohun tí mo ṣe sí ọ, ìwọ Gọ́ọ̀gù.—Ìsík. 38:16.

Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ó máa múnú bí àwọn tó ń ta ko Jèhófà. Torí náà, gbogbo orílẹ̀-èdè máa kóra jọ láti gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé. Ìbínú burúkú yìí ni Bíbélì pè ní ìkọlù látọ̀dọ̀ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù. (Ìsík. 38:​14, 15) Kí ni Jèhófà máa ṣe tí wọ́n bá gbéjà ko àwọn èèyàn rẹ̀? Ó sọ pé: “Inú á bí mi gidigidi.” (Ìsík. 38:​18, 21-23) Ìfihàn orí 19 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn. Jèhófà máa rán Ọmọ rẹ̀ láti gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀, kó sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. Bíbélì sọ pé “àwọn ọmọ ogun ọ̀run,” ìyẹn àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa dara pọ̀ mọ́ Jésù láti ja ogun náà. (Ìfi. 17:14; 19:​11-15) Kí ni ogun náà máa yọrí sí? Gbogbo àwọn tó ń ta ko Jèhófà máa pa run pátápátá!—Ìfi. 19:​19-21. w22.05 17 ¶9-10

Saturday, January 6

Màá mú kí ìwọ àti obìnrin náà di ọ̀tá ara yín.—Jẹ́n. 3:15.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó máa jẹ́ káwọn ọmọ wọn rí i pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Àsọtẹ́lẹ̀ náà wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Ó sọ pé: “Màá mú kí ìwọ àti obìnrin náà di ọ̀tá ara yín, ọmọ rẹ àti ọmọ rẹ̀ yóò sì di ọ̀tá. Òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì ṣe é léṣe ní gìgísẹ̀.” Inú ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì ni àsọtẹ́lẹ̀ náà wà. Àmọ́ gbogbo àwọn ìwé Bíbélì yòókù ló so mọ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí. Bí okùn ṣe máa ń so igi pọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣe so gbogbo àwọn ìwé Bíbélì yòókù pọ̀, wọ́n sì dá lórí ọ̀rọ̀ pàtàkì kan. Ọ̀rọ̀ pàtàkì náà ni pé Jèhófà máa rán Ẹnì kan tó máa gba aráyé, tó sì máa pa Èṣù àti àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ run. Ẹ ò rí i pé ìtura máa dé bá gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà! Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a máa rí bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ àti bó ṣe ń ṣe wá láǹfààní. w22.07 14 ¶1-3

Sunday, January 7

Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fúnni ní ọgbọ́n.—Òwe 2:6.

Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n tó o máa fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Jém. 1:5) Òun ló lè fún yín ní ìmọ̀ràn tó dáa jù lọ. Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, Jèhófà ni òbí tó mọ ọmọ tọ́ jù lọ. (Sm. 36:9) Ìkejì, kò sí ìgbà tí ìmọ̀ràn ẹ̀ kì í ṣe wá láǹfààní. (Àìsá. 48:17) Jèhófà ń lo Bíbélì àti ètò rẹ̀ láti pèsè ọ̀pọ̀ nǹkan tẹ́yin òbí lè lò láti fi kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Mát. 24:45) Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè rí àwọn ìmọ̀ràn tó máa ràn yín lọ́wọ́ nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé.” A tẹ àwọn àpilẹ̀kọ yìí jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ ní báyìí orí ìkànnì wa ló ti ń jáde. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ fídíò tó wà lórí ìkànnì jw.org ló ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti àṣefihàn tó máa jẹ́ kẹ́yin òbí mọ bí ẹ ṣe lè fi ìlànà Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ yín láti kékeré.—Òwe 2:​4, 5. w22.05 27 ¶4-5

Monday, January 8

Jáà, tó bá jẹ́ pé àṣìṣe lò ń wò . . . ta ló lè dúró?—Sm. 130:3.

Kò sẹ́ni tó lè dárí jini bíi ti Jèhófà. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe tán láti dárí jì wá. Ìdí kejì sì ni pé kò sí nǹkan tí kò mọ̀ nípa wa. Ó mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa irú ẹni tá a jẹ́ àtohun tó ń mú ká ṣe nǹkan. Torí náà, òun nìkan ló lè mọ̀ bóyá ẹnì kan ti ronú pìwà dà lóòótọ́ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìkẹta, tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ó máa ń gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ náà pátápátá. Ìyẹn ló máa ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó dáa, ká sì tún ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Òótọ́ kan ni pé tá a bá ṣì jẹ́ aláìpé, kò sí bá ò ṣe ní máa dẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀, ohun tó wà nínú ìwé Insight on the Scriptures lédè Gẹ̀ẹ́sì, Ìdìpọ̀ kejì, ojú ìwé 771 máa tù wá nínú. Ó sọ pé: “Aláàánú ni Jèhófà, ó sì mọ̀ pé àìpé máa ń jẹ́ káwa èèyàn ṣe nǹkan tí ò dáa nígbà míì. Torí náà, kò yẹ ká wá máa banú jẹ́ ṣáá pé à ń ṣàṣìṣe torí pé a jẹ́ aláìpé. (Sm. 103:​8-14; 130:3) Tá a bá ń ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe láti máa fi ìlànà Jèhófà sílò, a máa láyọ̀. (Flp 4:​4-6; 1Jo 3:​19-22).” w22.06 7 ¶18-19

Tuesday, January 9

Wọ́n máa mú yín lọ síwájú àwọn ọba àti àwọn gómìnà nítorí orúkọ mi.—Lúùkù 21:12.

Sátánì máa ń dá àwọn ọgbọ́n míì yàtọ̀ sí pé kó mú ká máa bẹ̀rù àwọn aláṣẹ ìjọba. Ní ti àwọn kan, ohun táwọn ìdílé wọn máa ṣe fún wọn tí wọ́n bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa ń bà wọ́n lẹ́rù ju ìyà tí ẹnikẹ́ni lè fi jẹ wọ́n lọ. Torí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ìdílé wọn gan-an, wọ́n fẹ́ káwọn náà wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà. Ó máa ń dùn wọ́n gan-an táwọn mọ̀lẹ́bí wọn bá ń sọ̀rọ̀ tí ò dáa nípa Jèhófà àtàwọn èèyàn ẹ̀. Síbẹ̀, àwọn mọ̀lẹ́bí tó ń ta ko àwọn ará wa kan tẹ́lẹ̀ ti wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́ tí ìdílé wa bá pa wá tì torí pé a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kí la máa ṣe? Òótọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 27:10 lè tù wá nínú gan-an. Tá a bá ń rántí bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa, ọkàn wa máa balẹ̀ táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa. Ó sì dá wa lójú pé ó máa san wá lẹ́san bá a ṣe ń fara dà á. Jèhófà nìkan ló lè pèsè gbogbo ohun tá a nílò nípa tara àtàwọn nǹkan táá jẹ́ ká máa jọ́sìn ẹ̀ nìṣó. w22.06 16-17 ¶11-13

Wednesday, January 10

Kristi . . . jìyà torí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín kí ẹ lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.—1 Pét. 2:21.

Nígbà tí Jésù ń ṣiṣẹ́ ìwàásù lórí ilẹ̀ ayé, àwọn èèyàn sọ pé ọ̀mùtí ni, wọ́n ní alájẹkì ni, wọ́n ní ìránṣẹ́ Èṣù ni, wọ́n ní kì í pa Sábáàtì mọ́ àti pé ó ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run. (Mát. 11:19; 26:65; Lúùkù 11:15; Jòh. 9:16) Síbẹ̀, Jésù ò sọ̀rọ̀ burúkú pa dà sí wọn. Bíi ti Jésù, táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wa, kò yẹ káwa náà sọ̀rọ̀ tí kò dáa pa dà sí wọn. (1 Pét. 2:​22, 23) Òótọ́ ni pé kì í rọrùn láti kó ara wa níjàánu tí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀ burúkú sí wa. (Jém. 3:2) Àmọ́ kí ló máa ràn wá lọ́wọ́? Tẹ́nì kan bá sọ̀rọ̀ tí ò dáa sí wa nígbà tá a wà lóde ẹ̀rí, ká gbìyànjú láti mọ ìdí tẹ́ni náà fi sọ̀rọ̀ lọ́nà yẹn. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Sam sọ pé: “Ohun tí mo máa ń fi sọ́kàn nípa ẹni tí mo fẹ́ wàásù fún ni bó ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àti pé ó ṣì lè yí pa dà.” Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ohun kan ti ṣẹlẹ̀ sí ẹni tá a fẹ́ wàásù fún ká tó débẹ̀. Tẹ́nì kan bá fìbínú sọ̀rọ̀ sí wa lóde ẹ̀rí, ṣe ló yẹ ká rọra gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ ká kó ara wa níjàánu ká má bàa sọ̀rọ̀ tí ò dáa sẹ́ni náà. w22.04 6 ¶8-9

Thursday, January 11

Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run.—Jém. 4:8.

Ohun pàtàkì kan tẹ́yin òbí lè ṣe láti mú káwọn ọmọ yín sún mọ́ Jèhófà ni pé kẹ́ ẹ máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (2 Tím. 3:​14-17) Àmọ́, Bíbélì tún sọ ọ̀nà míì táwọn ọmọ lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Nínú Bíbélì, ìwé Òwe sọ̀rọ̀ nípa bàbá kan tó ń rán ọmọ ẹ̀ létí pé kó má gbàgbé àwọn ànímọ́ Jèhófà tá a rí nínú àwọn nǹkan tó dá. (Òwe 3:​19-21) Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ló fẹ́ràn kí wọ́n máa mú àwọn ọmọ wọn ṣeré jáde. Torí náà, ẹ lo àkókò yẹn láti kọ́ àwọn ọmọ yín ní àwọn ànímọ́ rere Jèhófà tó wà nínú “àwọn ohun tó dá.” (Róòmù 1:20) Kíyè sí bí Jésù ṣe fi àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Nígbà kan, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n kíyè sí ẹyẹ ìwò àti òdòdó lílì. (Lúùkù 12:​24, 27-30) Ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nípa bí Bàbá wọn ọ̀run ṣe jẹ́ ọ̀làwọ́ àti onínúure. Ẹ̀kọ́ náà ni pé Jèhófà máa pèsè oúnjẹ àti aṣọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ bó ṣe pèsè oúnjẹ fáwọn ẹyẹ ìwò, tó sì wọ òdòdó lílì láṣọ. w23.03 20-21 ¶1-4

Friday, January 12

Ohunkóhun tí ẹ bá béèrè ní orúkọ mi, màá ṣe é, ká lè tipasẹ̀ Ọmọ yin Baba lógo.—Jòh. 14:13.

A dúpẹ́ pé a lè gbàdúrà sí Jèhófà nípasẹ̀ Ọmọ ẹ̀. Jésù sì ni Jèhófà máa ń lò láti dáhùn àwọn àdúrà wa. Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà ní orúkọ Jésù, Jèhófà máa ń gbọ́, ó sì máa ń dáhùn àdúrà wa. Jèhófà tún máa ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá nítorí ẹbọ ìràpadà Jésù. (Róòmù 5:1) Bíbélì sọ pé Jésù ni “àlùfáà àgbà [wa], ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọba Ọlọ́lá ní ọ̀run.” (Héb. 8:1) Jésù tún ni ‘olùrànlọ́wọ́ tó ń bá wa bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Baba.’ (1 Jòh. 2:1) A dúpẹ́, a tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún wa ní Àlùfáà Àgbà tó mọ àwọn àìlera wa, tó ń bá wa kẹ́dùn, “tó sì ń bá wa bẹ̀bẹ̀”! (Róòmù 8:34; Héb. 4:15) Tí kì í bá ṣe ẹbọ ìràpadà Jésù ni, kò bá má ṣeé ṣe fún wa láti gbàdúrà sí Jèhófà. Torí náà, kò sí nǹkan tá a lè fi san oore bàǹtàbanta tí Jèhófà ṣe wá, ìyẹn Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n tó fún wa, àfi ká ṣáà máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀! w22.07 23 ¶10-12

Saturday, January 13

Ẹni tó ṣeé fọkàn tán máa ń pa àṣírí mọ́.—Òwe 11:13.

Ẹni tó ṣeé fọkàn tán máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ó sì máa ń sọ òótọ́. (Sm. 15:4) Àwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn lè gbára lé e. Irú ẹni tá a sì fẹ́ káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa mọ̀ wá sí nìyẹn. A ò lè fipá mú àwọn èèyàn pé kí wọ́n fọkàn tán wa. Ìwà tá a bá ń hù ló máa jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa. Wọ́n máa ń sọ pé ohun tá a bá fara ṣiṣẹ́ fún ló ń pẹ́ lọ́wọ́ ẹni. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ fún un ni. Àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe ló jẹ́ ká fọkàn tán an. “Gbogbo ohun tó bá ṣe ló ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.” (Sm. 33:4) Jèhófà sì fẹ́ káwa náà fara wé òun. (Éfé. 5:1) A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá pé Jèhófà jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àti pé a wà lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kárí ayé tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì fọkàn tán ara wọn! Gbogbo wa ló yẹ ká máa ṣe ohun táá jẹ́ káwọn ará wa fọkàn tán wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fìfẹ́ hàn, ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká jẹ́ olóye, ká jẹ́ olóòótọ́, ká sì máa kó ara wa níjàánu. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká túbọ̀ máa fọkàn tán ara wa nínú ìjọ. Ẹ jẹ́ ká máa fara wé Jèhófà Ọlọ́run, ká sì máa ṣe ohun tó fi hàn pé a ṣeé fọkàn tán. w22.09 8 ¶1-2; 13 ¶17

Sunday, January 14

Jèhófà ń ṣọ́ [wa].—Sm. 33:18.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a láwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tá a jọ ń sin Jèhófà, ó ṣì máa ń ṣe wá bíi pé a dá wà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. A lè bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀wẹ̀sì, ká sì rò pé a lè yanjú ìṣòro náà fúnra wa. Àmọ́, Jèhófà ò fẹ́ ká máa ronú bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣe fún wòlíì Èlíjà. Jèhófà jẹ́ kí Èlíjà sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀. Ẹ̀ẹ̀mejì ni Jèhófà béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: “Kí lò ń ṣe níbí?” (1 Ọba 19:​9, 13) Jèhófà fara balẹ̀ tẹ́tí sí Èlíjà láwọn ìgbà tó ń sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ̀. Ó tún fi dá Èlíjà lójú pé òun nìkan kọ́ ló ṣẹ́ kù tó ń sin òun. (1 Ọba 19:​11, 12, 18) Kò sí àní-àní pé nígbà tí Èlíjà sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀, tí Jèhófà sì jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn míì ṣì wà tó ń jọ́sìn òun, ara tù ú. Jèhófà wá gbé àwọn iṣẹ́ kan tó ṣe pàtàkì fún Èlíjà. Ó ní kó yan Hásáẹ́lì láti di ọba Síríà, kó yan Jéhù ṣe ọba Ísírẹ́lì, kó sì sọ Èlíṣà di wòlíì. (1 Ọba 19:​15, 16) Àwọn iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Èlíjà yìí ò ní jẹ́ kó máa rò pé òun dá wà mọ́. Jèhófà tún ní kí òun àti Èlíṣà jọ máa ṣiṣẹ́, wọ́n sì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. w22.08 8 ¶3; 9 ¶5

Monday, January 15

Ẹ máa fún ara yín níṣìírí, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró.—1 Tẹs. 5:11.

Ṣé ìjọ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba yín ni àbí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ tún un ṣe? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá rántí ìpàdé àkọ́kọ́ tó o ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun náà. Ṣe ni inú ẹ ń dùn, tó o sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Kódà, inú ẹ dùn gan-an débi pé omijé ayọ̀ ń bọ́ lójú ẹ, kò sì rọrùn fún ẹ láti kọrin tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ ìpàdé lọ́jọ́ yẹn. Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó rẹwà tá a kọ́ máa ń mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà. Àmọ́, a máa mú ìyìn tó ga jù lọ bá orúkọ Jèhófà tá a bá ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì míì tó ní ká máa ṣe. Iṣẹ́ yìí ṣe pàtàkì ju iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ. Iṣẹ́ náà ni pé tá a bá wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ká máa gbé àwọn ará wa ró. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó kọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká gbé àwọn ará ró. Ó máa ń gba tiwọn rò. Lónìí, àwa náà lè fara wé Pọ́ọ̀lù, ká máa gbé àwọn ará wa ró.—1 Kọ́r. 11:1. w22.08 20 ¶1-2

Tuesday, January 16

Ẹ máa rìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà.—Kól. 1:10.

Tí Kristẹni kan bá fẹ́ jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ nídìí iṣẹ́ tó ń ṣe. Ẹni tó jẹ́ olódodo máa ń ṣèdájọ́ òdodo, inú ẹ̀ kì í sì í dùn tí wọ́n bá rẹ́ àwọn ẹlòmíì jẹ. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń ronú lórí ojú tí Jèhófà máa fi wo nǹkan tóun fẹ́ ṣe torí pé ó fẹ́ “ṣe ìfẹ́ [Jèhófà] ní kíkún.” Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni òdodo ti wá. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Jèhófà ní “ibùgbé òdodo.” (Jer. 50:7) Torí pé Jèhófà ló dá wa, òun nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ bóyá ohun kan tọ́ tàbí kò tọ́. Àwa èèyàn kì í mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Àmọ́ Jèhófà máa ń mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Òwe 14:12; Àìsá. 55:​8, 9) Torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara ẹ̀, ìyẹn mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo ẹ̀. (Jẹ́n. 1:27) Ó sì máa ń wu àwa náà pé ká ṣe ohun tó tọ́. Torí náà, ìfẹ́ tá a ní fún Bàbá wa ọ̀run ló ń mú ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fìwà jọ ọ́.—Éfé. 5:1. w22.08 27 ¶5-6

Wednesday, January 17

Ẹ máa fi òye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.—Éfé. 5:17.

Tí ohun kan bá ń kó wa lọ́kàn sókè tàbí tá a rẹ̀wẹ̀sì, ó máa ń wù wá ká ṣe ohun tá a máa fi pàrònú rẹ́. Bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn, àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, kó má lọ jẹ́ ohun tínú Jèhófà ò dùn sí la máa fi pàrònú rẹ́. (Éfé. 5:​10-12, 15, 16) Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Fílípì, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa ronú nípa ohunkóhun tó jẹ́ ‘òdodo, tó jẹ́ mímọ́, tó yẹ ní fífẹ́ àti ohunkóhun tó bá dára.’ (Fílí. 4:8) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé eré ìnàjú kọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, ohun tó sọ lè ràn wá lọ́wọ́ láti yan eré ìnàjú tó dáa. Tó o bá ń ka ẹsẹ yìí, gbìyànjú kó o ṣe nǹkan yìí: Ibi tó o bá ti rí ọ̀rọ̀ náà “ohunkóhun,” fi “orin,” “fíìmù,” “ìwé” tàbí “géèmù orí kọ̀ǹpútà” rọ́pò ẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ kó o mọ eré ìnàjú tí Ọlọ́run fẹ́ àtèyí tí kò fẹ́. Àwọn ìlànà gíga Jèhófà la fẹ́ máa tẹ̀ lé nígbèésí ayé wa.—Sm. 119:​1-3. w22.10 9 ¶11-12

Thursday, January 18

Ó mọ ohun tó wà nínú èèyàn.—Jòh. 2:25.

Kí àwọn “aláìṣòdodo” kan tó kú, ìwà tó burú jáì ló kún ọwọ́ wọn. Torí náà, ó máa gba pé ká kọ́ wọn láwọn òfin àti ìlànà Jèhófà, kí wọ́n lè máa fi sílò. Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, Ìjọba Ọlọ́run máa ṣètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá ò ṣe irú ẹ̀ rí nínú ìtàn aráyé. Àwọn wo ló máa kọ́ àwọn aláìṣòdodo lẹ́kọ̀ọ́? Ogunlọ́gọ̀ èèyàn àtàwọn olódodo tí Jèhófà jí dìde ló máa kọ́ wọn. Torí náà, kí Jèhófà tó lè kọ orúkọ àwọn aláìṣòdodo sínú ìwé ìyè, wọ́n gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀, kí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ fún un. Jésù Kristi àtàwọn ẹni àmì òróró á máa fara balẹ̀ kíyè sí àwọn aláìṣòdodo yìí látọ̀run bóyá wọ́n ń fi nǹkan tí wọ́n ń kọ́ sílò. (Ìfi. 20:4) Jèhófà máa pa ẹnikẹ́ni tí ò bá fi àwọn nǹkan tó ń kọ́ sílò, bó tiẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún péré. (Àìsá. 65:20) Jèhófà àti Jésù mọ ohun tó wà lọ́kàn àwa èèyàn, torí náà wọ́n máa rí i dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tó máa fa ìpalára kankan nínú ayé tuntun.—Àìsá. 11:9; 60:18; 65:25. w22.09 17 ¶11-12

Friday, January 19

Kí gbogbo èèyàn máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga.—Róòmù 13:1.

Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, gbólóhùn náà, “àwọn aláṣẹ onípò gíga” ń tọ́ka sí àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso, tí wọ́n sì ń lo agbára wọn láti darí àwọn èèyàn. Àwa Kristẹni tòótọ́ náà wà lára àwọn tó gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ ìjọba yìí. Ìdí ni pé wọ́n máa ń ṣe ipa tiwọn kí àlàáfíà lè wà nílùú, wọ́n máa ń rí i dájú pé àwọn èèyàn ń pa òfin ìlú mọ́, nígbà míì sì rèé, wọ́n máa ń gbèjà àwa èèyàn Ọlọ́run. (Ìfi. 12:16) Torí náà, Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa san owó orí fún wọn, ká máa fún wọn ní ìṣákọ́lẹ̀, ká máa bẹ̀rù wọn bó ṣe yẹ, ká sì máa bọlá fún wọn. (Róòmù 13:7) Àmọ́ torí pé Jèhófà fàyè gba àwọn aláṣẹ ìjọba yìí ni wọ́n ṣe ń lo àṣẹ wọn lórí àwọn èèyàn. Jésù jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà tí gómìnà Róòmù kan tó ń jẹ́ Pọ́ńtíù Pílátù ń bi í láwọn ìbéèrè kan. Nígbà tí Pílátù ń sọ fún Jésù pé òun láṣẹ láti sọ pé kí wọ́n pa á tàbí kí wọ́n dá a sílẹ̀, Jésù sọ fún un pé: “O ò lè ní àṣẹ kankan lórí mi àfi tí a bá fún ọ láṣẹ látòkè.” (Jòh. 19:11) Bákan náà ló rí lónìí, bíi ti Pílátù, ó níbi tí agbára àwọn aláṣẹ ayé yìí mọ. w22.10 14 ¶6

Saturday, January 20

Àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́.—Sm. 37:10.

Ọlọ́run fẹ̀mí ẹ̀ darí Ọba Dáfídì láti sọ bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà tí ọba kan tó jẹ́ olóòótọ́ àti ọlọ́gbọ́n bá ń ṣàkóso lọ́jọ́ iwájú. (Sm. 37:​10, 11, 29) A sábà máa ń ka Sáàmù 37:11 fáwọn èèyàn tá a bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Párádísè tó ń bọ̀. Ìyẹn dáa gan-an torí Jésù náà lo ẹsẹ Bíbélì yẹn nínú Ìwàásù orí Òkè, tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ yẹn ṣì máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. (Mát. 5:5) Àmọ́ ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ tún jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí Ọba Sólómọ́nì bá ń ṣàkóso. Nígbà tí Sólómọ́nì di ọba Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn Ọlọ́run gbádùn àlàáfíà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, wọ́n sì rí gbogbo nǹkan tí wọ́n nílò ní ilẹ̀ “tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.” Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Tí ẹ bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin mi . . . , màá mú kí àlàáfíà wà ní ilẹ̀ náà, ẹ ó sì dùbúlẹ̀ láìsí ẹni tó máa dẹ́rù bà yín.” (Léf. 20:24; 26:​3, 6) Gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ló ṣẹ nígbà àkóso Sólómọ́nì. (1 Kíró. 22:9; 29:​26-28) Torí náà, ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 37:​10, 11, 29 ṣẹ nígbà àtijọ́, ó sì tún máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. w22.12 10 ¶8

Sunday, January 21

Aláyọ̀ ni a ó máa pe àwọn tó di [ọgbọ́n] mú ṣinṣin.—Òwe 3:18.

Torí pé Kristẹni tòótọ́ ni wá, ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ètò Ọlọ́run. Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn kan tó máa jẹ́ ká ṣàṣeyọrí, ó ní: “Ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n ni kí o fi ja ogun rẹ, nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.” (Òwe 24:​6, àlàyé ìsàlẹ̀) Ẹ jẹ́ ká wo bí ìlànà Bíbélì yìí ṣe ń jẹ́ ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni tá à ń ṣe. Dípò ká máa ṣiṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni lọ́nà tó wù wá, à ń tẹ̀ lé àbá tí ètò Ọlọ́run ń fún wa. À ń rí ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n gbà láwọn ìpàdé wa torí pé ibẹ̀ ni àwọn tó ní ìrírí ti máa ń sọ àsọyé tó dá lórí Bíbélì, a sì tún máa ń gbádùn àṣefihàn tó ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ètò Ọlọ́run máa ń ṣe àwọn ìwé àtàwọn fídíò tó wúlò láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ òtítọ́ Bíbélì. A mà dúpẹ́ o pé àwọn ìmọ̀ràn tó ń ṣe wá láǹfààní wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! Báwo layé wa ò bá ṣe rí ká sọ pé àwọn ìmọ̀ràn yìí ò sí nínú Bíbélì? Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé jálẹ̀ ìgbésí ayé wa làá máa lo ọgbọ́n tí Jèhófà fún wa.—Òwe 3:​13-17. w22.10 23 ¶18-19

Monday, January 22

Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ mà dùn mọ́ òkè ẹnu mi o, ó dùn ju oyin lọ lẹ́nu mi.—Sm. 119:103.

Tá a bá jẹ oúnjẹ kan, tó sì dà lára wa, ó máa ń ṣara wa lóore. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá à ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára. Jèhófà fẹ́ kí ọ̀rọ̀ òun yé wa dáadáa. Bá a ṣe lè ṣe é ni pé ká máa gbàdúrà, ká máa ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ẹ̀. Tá a bá fẹ́ ka Bíbélì, ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe ni pé ká gbàdúrà kóun tá a fẹ́ kà lè wọ̀ wá lọ́kàn. Lẹ́yìn náà, àá bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Ohun tó kàn ni pé ká dánu dúró láwọn ibi tó yẹ, ká ṣàṣàrò, ká sì ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àǹfààní wo la máa rí? Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á yé wa dáadáa, ìgbàgbọ́ wa á sì túbọ̀ lágbára. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ka Bíbélì, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ẹ̀? Ìdí ni pé tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, á sì jẹ́ ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run nìṣó. Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ ká nígboyà láti kéde gbankọgbì ọ̀rọ̀ ìdájọ́ lọ́jọ́ iwájú. Bákan náà, tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ Jèhófà, á mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. w22.11 6-7 ¶16-17

Tuesday, January 23

Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.—Jòh. 13:35.

Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe àwa nìkan la máa mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ ni wá, àwọn tí kì í ṣe Kristẹni tòótọ́ náà máa mọ̀ bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá rí ìfẹ́ tòótọ́ tó wà láàárín wa. Ìfẹ́ tó sì wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà láwọn ìjọ wa ṣàrà ọ̀tọ̀. Ká sòótọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ẹni pípé. (1 Jòh. 1:8) Torí náà, bá a bá ṣe ń mọ àwọn ará ìjọ sí i, bẹ́ẹ̀ làá máa rí kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. (Róòmù 3:23) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn kan ti jẹ́ kí àìpé àwọn ará wa mú kí wọ́n má sin Jèhófà mọ́. Báwo ni Jésù ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn àpọ́sítélì ẹ̀? Ṣé ó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn lónìí láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? Ó yẹ káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ronú dáadáa ká tó dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè túbọ̀ fìfẹ́ hàn sáwọn ará tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá.—Éfé. 5:2. w23.03 26-27 ¶2-4

Wednesday, January 24

Ìwọ jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin.—Sm. 18:25.

Bá a ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ó dájú pé àwọn ará ìjọ á máa ṣe àwọn nǹkan tó dùn wá. Àwọn nǹkan yẹn sì lè jẹ́ ká mọ̀ bóyá a máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ronú lọ́nà tó tọ́. Tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ ẹ́ nínú ìjọ, má di ẹni náà sínú. Tí wọ́n bá bá ẹ wí tí ìbáwí náà sì kó ìtìjú bá ẹ, àǹfààní tó máa ṣe ẹ́ ni kó o wò. Torí náà gba ìbáwí náà, kó o sì ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Yàtọ̀ síyẹn, tí àyípadà bá wáyé nínú ètò Ọlọ́run tó kan iṣẹ́ tó ò ń ṣe, rí i pé o fara mọ́ àwọn àyípadà náà, kó o sì kọ́wọ́ ti ètò tí wọ́n ṣe. Jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò rẹ̀ táwọn nǹkan kan bá dán ìgbàgbọ́ ẹ wò. Máa fara balẹ̀, máa ronú jinlẹ̀, kó o sì máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, má sì ya ara ẹ sọ́tọ̀ nínú ìjọ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò sóhun tí Sátánì lè ṣe táá jẹ́ kó o fi Jèhófà àti ètò ẹ̀ sílẹ̀.—Jém. 4:7. w22.11 24-25 ¶14-16

Thursday, January 25

Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará.—1 Pét. 2:17.

Ẹ̀yin alàgbà, ẹ ran àwọn ará tó wà níjọ yín lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de àjálù. Ẹ rí i pé gbogbo àwọn ará mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láti dáàbò bo ara wọn àti bí wọ́n ṣe máa kàn sáwọn alàgbà. Kí ló yẹ kíwọ fúnra ẹ ṣe? Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ nítòsí ibi tó ò ń gbé, béèrè àwọn nǹkan tó o lè ṣe lọ́wọ́ àwọn alàgbà. O lè ní káwọn tí ilé wọn bà jẹ́ tàbí àwọn tó sá kúrò nílé torí àjálù wá gbélé ẹ fúngbà díẹ̀, o sì tún lè gba àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti wá ṣèrànwọ́ sílé ẹ. O tún lè máa bá wọn pín oúnjẹ àtàwọn ohun èlò míì fáwọn ará. Tó bá sì jẹ́ pé ibi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀ jìnnà díẹ̀ síbi tó ò ń gbé, o ṣì lè ṣèrànwọ́. Lọ́nà wo? O lè máa gbàdúrà fáwọn tí àjálù dé bá. (2 Kọ́r. 1:​8-11) O lè fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ wa kárí ayé kí wọ́n lè fi tọ́jú àwọn tí àjálù dé bá. (2 Kọ́r. 8:​2-5) Tó o bá máa ráyè rìnrìn àjò lọ síbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ láti ṣèrànwọ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà bóyá o lè yọ̀ǹda ara ẹ. Tí wọ́n bá pè ẹ́ pé kó o wá ṣèrànwọ́, wọ́n máa dá ẹ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè lò ẹ́ níbi tó o ti máa wúlò gan-an. w22.12 24 ¶8; 25 ¶11-12

Friday, January 26

Kò sí àdánwò kankan tó ti bá yín àfi èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn.—1 Kọ́r. 10:13.

Bíbélì sọ pé: “Kò sí àdánwò kankan tó ti bá yín àfi èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn.” Àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó gbé nílùú Kọ́ríńtì la darí ọ̀rọ̀ yìí sí. Àwọn kan lára wọn ti jẹ́ alágbèrè, abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ àti ọ̀mùtípara rí. (1 Kọ́r. 6:​9-11) Ṣé o rò pé lẹ́yìn tí wọ́n ṣèrìbọmi, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ kankan ò wá sí wọn lọ́kàn? Rárá o. Òótọ́ ni pé Kristẹni ẹni àmì òróró ni gbogbo wọn, síbẹ̀ aláìpé ni wọ́n. Ó dájú pé àtìgbàdégbà làwọn náà á máa gbógun ti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Ó yẹ kí àpẹẹrẹ wọn yìí fún wa níṣìírí. Kí nìdí? Ìdí ni pé àpẹẹrẹ tí wọ́n fi lélẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yòówù ká máa bá jà báyìí, àwọn kan ti borí ẹ̀ rí. Torí náà, ó dájú pé a lè ‘dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ torí pé irú ìyà kan náà ló ń jẹ gbogbo àwọn ará wa.’—1 Pét. 5:9. w23.01 12 ¶15

Saturday, January 27

Ẹ máa ní ìpọ́njú nínú ayé, àmọ́ ẹ mọ́kàn le! Mo ti ṣẹ́gun ayé.—Jòh. 16:33.

Jésù bẹ Jèhófà pé kó máa ṣọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. (Jòh. 17:11) Báwo ni ohun tí Jésù sọ yìí ṣe jẹ́ ká nígboyà? Ó jẹ́ ká nígboyà torí a mọ̀ pé Jèhófà lágbára ju àwọn ọ̀tá wa lọ. (1 Jòh. 4:4) Ó ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Torí náà, ó dájú pé tá a bá gbára lé Jèhófà, ó máa jẹ́ ká nígboyà láti borí àwọn nǹkan tó ń bà wá lẹ́rù. Tó o bá wà nílé ìwé tàbí níbi iṣẹ́, ṣé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́ nígbà míì láti sọ fáwọn èèyàn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́? Ṣé torí o ò mọ ohun táwọn èèyàn máa rò nípa ẹ ni ò jẹ́ kó o di akéde tí ò tíì ṣèrìbọmi tàbí kó o ṣèrìbọmi? Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́. Gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ nígboyà láti ṣe ohun tó fẹ́. Tó o bá ti ń rí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà ẹ, ọkàn ẹ á balẹ̀, wàá sì túbọ̀ nígboyà.—Àìsá. 41:​10, 13. w23.01 29 ¶12; 30 ¶14

Sunday, January 28

Ṣé ẹ ò tíì kà á ni?—Mát. 12:3.

Jésù bi àwọn Farisí pé, ‘Ṣé ẹ ò tíì kà á ni?’ kó lè fi hàn pé wọn ò lóye ohun tí wọ́n ń kà nínú Ìwé Mímọ́. (Mát. 12:​1-7) Lọ́jọ́ tá à ń wí yìí, ṣe làwọn Farisí fẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pé wọ́n rú òfin Sábáàtì. Torí náà, Jésù tọ́ka sí àpẹẹrẹ méjì látinú Ìwé Mímọ́, ó sì fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé Hósíà kó lè fi hàn pé àwọn Farisí yẹn ò lóye òfin Sábáàtì, wọn ò sì lójú àánú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Farisí yẹn ń ka Ìwé Mímọ́, kí nìdí tí wọn ò fi jẹ́ kó yí èrò wọn pa dà? Ìdí ni pé wọ́n ń gbéra ga, bí wọ́n sì ṣe máa fi dá àwọn ẹlòmíì lẹ́jọ́ ni wọ́n máa ń wá tí wọ́n bá ń ka Ìwé Mímọ́. Ìwà burúkú tí wọ́n ní yìí ni ò jẹ́ kí wọ́n lóye ohun tí wọ́n ń kà. (Mát. 23:23; Jòh. 5:​39, 40) Tún kíyè sí Mátíù 19:​4-6, níbi tí Jésù ti bi àwọn Farisí pé: “Ṣé ẹ ò kà á pé?” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kà nípa bí Jèhófà ṣe dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, wọn ò lóye ojú tí Jèhófà fi ń wo ìgbéyàwó. Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ ní èrò tó tọ́ tá a bá ń ka Bíbélì. Kò yẹ ká ṣe bíi tàwọn Farisí, ó yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì ṣe tán láti gba ẹ̀kọ́. w23.02 12 ¶12-13

Monday, January 29

Làákàyè yóò máa ṣọ́ ọ.—Òwe 2:11.

Nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó fún wọn láwọn ìlànà tí ò ní jẹ́ kí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí wọn nílé àti níbi iṣẹ́. (Ẹ́kís. 21:​28, 29; Diu. 22:8) Ìdí sì ni pé tẹ́nì kan bá ṣèèṣì pa ẹlòmíì, ó máa jìyà ẹ̀. (Diu. 19:​4, 5) Kódà, Òfin yẹn sọ pé wọ́n máa fìyà jẹ ẹni tó bá ṣe ọmọ inú aláboyún léṣe bí ò tiẹ̀ mọ̀ọ́mọ̀. (Ẹ́kís. 21:​22, 23) Torí náà, Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ààbò. A máa fi hàn pé a mọyì ìwàláàyè tí Ọlọ́run fún wa tá a bá fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ààbò nílé àti níbi iṣẹ́. Tá a bá fẹ́ kó ọ̀bẹ, àwọn nǹkan tó mú, oògùn àtàwọn kẹ́míkà dà nù, ibi tí ò ti ní pa ẹnikẹ́ni lára ló yẹ ká kó wọn dà nù sí, kò sì yẹ ká kó irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ síbi tọ́wọ́ àwọn ọmọdé ti lè tó o. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká ṣọ́ra gan-an tá a bá wà nídìí iná tó ń jó, omi gbígbóná àtàwọn nǹkan tó ń báná ṣiṣẹ́, ká má sì fi àwọn nǹkan yẹn sílẹ̀ láì bójú tó wọn. Bákan náà, kò yẹ ká wa mọ́tò tàbí ọ̀kadà tá a bá mutí, tá ò bá sùn dáadáa tàbí tá a bá lo oògùn tó lè ṣe ojú wa bàìbàì. Yàtọ̀ síyẹn, kò yẹ ká máa lo fóònù wa tá a bá ń wa mọ́tò. w23.02 21-22 ¶7-9

Tuesday, January 30

O sì máa fi ojú ara rẹ rí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá.—Àìsá. 30:20.

Jèhófà jẹ́ Olùkọ́ tó máa ń ní sùúrù, tó nínúure, tó sì máa ń gba tàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ rò. Ibi táwọn akẹ́kọ̀ọ́ dáa sí ló máa ń wò. (Sm. 130:3) Kì í sì í retí pé ká ṣe kọjá ohun tágbára wa gbé. Máa rántí pé òun ló ṣẹ̀dá ọpọlọ rẹ, ẹ̀bùn àgbàyanu ló sì jẹ́. (Sm. 139:14) Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ títí láé ká sì máa gbádùn ẹ̀. Torí náà, tá a bá jẹ́ kó ‘máa wù wá gan-an’ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ báyìí, ohun tó bọ́gbọ́n mu là ń ṣe yẹn. (1 Pét. 2:2) Ní àwọn àfojúsùn tọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀, kó o sì máa tẹ̀ lé ètò tó o ṣe láti máa ka Bíbélì àtèyí tó o ṣe láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́. (Jóṣ. 1:8) Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa gbádùn ohun tó ò ń kà, ìyẹn á sì jẹ́ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà. Kéèyàn nímọ̀ nìkan ò tó. Ìdí tí ìmọ̀ fi ṣe pàtàkì ni pé ó máa jẹ́ kó o mọ Jèhófà sí i, kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú ẹ̀ sì túbọ̀ lágbára. (1 Kọ́r. 8:​1-3) Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o nígbàgbọ́ sí i. (Lúùkù 17:5) Ó dájú pé Jèhófà máa dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀. w23.03 10 ¶11, 13

Wednesday, January 31

Ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.—Kól. 4:5.

Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe ń dúró dìgbà tí òpin máa dé, ó yẹ kí wọ́n jẹ́ kí ọwọ́ wọn dí torí pé Jésù ti gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún wọn. Ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run “ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:​6-8) Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ńlá ni Jésù gbé fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Torí náà, tí wọ́n bá ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti wàásù fáwọn èèyàn, ìyẹn á fi hàn pé wọ́n ń lo àkókò wọn lọ́nà tó dáa jù lọ. Tá a bá fẹ́ máa kíyè sí ara wa, ó yẹ ká ronú nípa ohun tá à ń fi àkókò wa ṣe. Ìdí sì ni pé “ìgbà àti èèṣì” lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni nínú wa. (Oníw. 9:11) Yàtọ̀ síyẹn, ìgbàkigbà la lè kú. A lè lo àkókò wa lọ́nà tó dáa jù lọ tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, tá a sì ń mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ lágbára sí i. (Jòh. 14:21) Ó yẹ ká ‘dúró gbọn-in, ká má yẹsẹ̀, ká sì máa ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo.’ (1 Kọ́r. 15:58) Torí náà tí òpin bá dé, bóyá òpin ayé búburú yìí ni o tàbí a kú, a ò ní kábàámọ̀ pé a fi àkókò wa ṣe ìfẹ́ Jèhófà.—Mát. 24:13; Róòmù 14:8. w23.02 18 ¶12-14

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́