ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es24 ojú ìwé 6
  • Bó O Ṣe Máa Lo Ìwé Yìí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Máa Lo Ìwé Yìí
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
  • Ìsọ̀rí
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
es24 ojú ìwé 6

Bó O Ṣe Máa Lo Ìwé Yìí

Nínú àwọn ojú ìwé tó tẹ̀ lé e, wàá rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àti àlàyé tá a ṣe lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbàkigbà lo lè ka ẹsẹ ojúmọ́ àti àlàyé tá a ṣe lórí ẹ̀, àwọn kan ti rí i pé ó ṣàǹfààní gan-an téèyàn bá kà á láàárọ̀. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè ronú lórí ohun tí wọ́n kà jálẹ̀ ọjọ́ náà. Ohun tó ṣàǹfààní jù ni pé kí ìdílé jọ ka ẹsẹ ojúmọ́ pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà oúnjẹ àárọ̀ làwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì kárí ayé máa ń ka ẹsẹ ojúmọ́.

Inú Ilé Ìṣọ́ (w) April 2022 sí March 2023 la ti mú àwọn àlàyé tá a ṣe lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà jáde. Nọ́ńbà tó tẹ̀ lé Ilé Ìṣọ́ ń tọ́ka sí ojú ìwé tá a ti mú àlàyé náà jáde. Lẹ́yìn ìyẹn, wàá rí nọ́ńbà ìpínrọ̀ tó o ti lè rí àfikún àlàyé nínú Ilé Ìṣọ́. (Wo àpẹẹrẹ tó wà nísàlẹ̀.) Inú àpilẹ̀kọ tá a ti mú àlàyé jáde lo ti máa rí àfikún ìsọfúnni lórí kókó ọ̀rọ̀ tá a bá gbé yẹ̀ wò.

[Àwòrán ojú ìwé 6]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́