March
Friday, March 1
Kí ló dé tí ò ń fọ́nnu?—1 Kọ́r. 4:7.
Àpọ́sítélì Pétérù rọ àwọn ará pé kí wọ́n lo ẹ̀bùn èyíkéyìí tí wọ́n bá ní láti fi ran àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́. Ó sọ nínú lẹ́tà náà pé: “Bí kálukú bá ṣe ń rí ẹ̀bùn gbà, ẹ máa fi ṣe ìránṣẹ́ fún ara yín bí ìríjú àtàtà tó ń rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run gbà.” (1 Pét. 4:10) Kò yẹ ká máa bẹ̀rù láti lo ẹ̀bùn tá a ní bóyá torí a rò pé àwọn èèyàn máa jowú wa tàbí ká máa rò pé ìrẹ̀wẹ̀sì á mú wọn torí wọn ò nírú ẹ̀bùn tá a ní. Àmọ́ kò yẹ ká máa fọ́nnu nípa ẹ̀. (1 Kọ́r. 4:6) Ẹ jẹ́ ká máa fi sọ́kàn pé Jèhófà ló fún wa ní gbogbo ẹ̀bùn tá a ní. Torí náà, ó yẹ ká lo àwọn ẹ̀bùn wa láti gbé àwọn ará ró, kì í ṣe pé ká máa fi gbé ara wa lárugẹ. (Fílí. 2:3) Tá a bá ń lo okun àti ẹ̀bùn tá a ní láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, inú wa máa dùn. Kì í ṣe torí pé a fẹ́ fi hàn pé a mọ nǹkan ṣe ju àwọn míì lọ tàbí pé a dáa jù wọ́n lọ la ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a fẹ́ fi àwọn ẹ̀bùn tá a ní yin Jèhófà lógo. w22.04 11-12 ¶7-9
Saturday, March 2
La ojú mi kí n lè rí àwọn ohun àgbàyanu tó wà nínú òfin rẹ kedere.—Sm. 119:18.
Jésù nífẹ̀ẹ́ Ìwé Mímọ́ gan-an, kódà Sáàmù 40:8 sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ní: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run mi, ni inú mi dùn sí, òfin rẹ sì wà nínú mi lọ́hùn-ún.” Torí pé Jésù nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà, ó fayọ̀ sin Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. Táwa náà bá ń jẹ́ kí ohun tá à ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ wá lọ́kàn, tá a sì ń fi sílò, àwa náà máa láyọ̀, a ò sì ní fi Jèhófà sílẹ̀. (Sm. 1:1-3) Ohun tí Jésù sọ àti àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ ti jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká wá bá a ṣe máa jàǹfààní púpọ̀ sí i tá a bá ń ka Bíbélì. A máa túbọ̀ lóye ohun tá à ń kà nínú Bíbélì tá a bá ń gbàdúrà, tá à ń fara balẹ̀ ka Bíbélì, tá à ń béèrè àwọn ìbéèrè tó yẹ, tá a sì ń ṣàkọsílẹ̀. Ó tún yẹ ká máa fòye mọ ohun tá à ń kà nínú Bíbélì, ká máa ronú jinlẹ̀ lórí ẹ̀, ká sì ṣèwádìí nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ká ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ bá a ṣe ń kà á. Torí náà, tá a bá ń fi gbogbo àbá yìí sílò bá a ṣe ń ka Bíbélì, àá jàǹfààní nínú ohun tá à ń kà. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Bàbá wa ọ̀run.—Sm. 119:17; Jém. 4:8. w23.02 13 ¶15-16
Sunday, March 3
Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.—Òwe 21:5.
Ní ohun kan lọ́kàn tó o fẹ́ ṣe, kó o sì ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀ ẹ́. Báwo lo ṣe máa ṣe é? Ká sọ pé o fẹ́ jẹ́ kí ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́ni dáa sí i. Fara balẹ̀ ka ìwé Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni. Tí wọ́n bá fún ẹ níṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀, o lè ṣiṣẹ́ náà fún arákùnrin kan tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ṣáájú ọjọ́ yẹn, kó o sì ní kó fún ẹ nímọ̀ràn tó máa jẹ́ kó o sunwọ̀n sí i. Máa múra iṣẹ́ ẹ sílẹ̀ dáadáa káwọn ará lè gbádùn ẹ̀, kí wọ́n sì rí i pé o ṣe é gbára lé. (2 Kọ́r. 8:22) Ká sọ pé nǹkan tó o fẹ́ ṣiṣẹ́ lé ò rọrùn fún ẹ ńkọ́? Má jẹ́ kó sú ẹ! Ṣé Tímótì di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́ tàbí olùkọ́ tó ta yọ? Bíbélì ò sọ fún wa. Àmọ́ Tímótì ń tẹ̀ síwájú, ó sì fọwọ́ gidi mú iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un torí ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù.—2 Tím. 3:10. w22.04 24-25 ¶8-11
Monday, March 4
Mo wá rí ẹranko kan tó ń jáde látinú òkun, ó ní ìwo mẹ́wàá àti orí méje.—Ìfi. 13:1.
Kí ni ẹranko ẹhànnà olórí méje náà? A kíyè sí pé ẹranko náà dà bí àmọ̀tẹ́kùn, àmọ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bíi ti bíárì, ẹnu rẹ̀ jọ ti kìnnìún, ó sì ní ìwo mẹ́wàá. Gbogbo nǹkan yìí làwọn ẹranko mẹ́rin tó wà nínú Dáníẹ́lì orí 7 ní. Àmọ́ nínú ìwé Ìfihàn, ẹranko kan ṣoṣo ló ní gbogbo nǹkan yìí kì í ṣe ẹranko mẹ́rin. Ẹranko ẹhànnà kan ṣoṣo yẹn ò ṣàpẹẹrẹ ìjọba kan ṣoṣo tàbí ìjọba alágbára kan tó ń ṣàkóso gbogbo ayé. Jòhánù sọ pé ó ń ṣàkóso lórí “gbogbo ẹ̀yà, èèyàn, ahọ́n àti orílẹ̀-èdè.” Ẹranko yìí lágbára ju ìjọba orílẹ̀-èdè èyíkéyìí lọ. (Ìfi. 13:7) Torí náà, ẹranko ẹhànnà yìí ṣàpẹẹrẹ gbogbo àwọn ìjọba alágbára tó ṣàkóso ayé jálẹ̀ ìtàn aráyé. (Oníw. 8:9) Ẹ̀rí míì ni pé Bíbélì sábà máa ń lo nọ́ńbà náà mẹ́wàá láti fi hàn pé ohun kan pé pérépéré. w22.05 9 ¶6
Tuesday, March 5
Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.—Ìfi. 21:4.
Àwọn wo ló máa jàǹfààní àwọn ohun rere yìí? Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó la Amágẹ́dọ́nì já àtàwọn ọmọ tí wọ́n bá bí nínú ayé tuntun. Àmọ́, Ìfihàn orí 20 ṣèlérí pé Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde. (Ìfi. 20:11-13) Torí náà, gbogbo àwọn “olódodo” tí wọ́n ti kú àtàwọn “aláìṣòdodo” tí wọn ò láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ló máa jíǹde sí ayé. (Ìṣe 24:15; Jòh. 5:28, 29) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó bá kú ló máa jíǹde nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà? Rárá o. Àwọn tó bá ṣorí kunkun pé àwọn ò ní sin Jèhófà kí wọ́n tó kú ò ní jíǹde. Wọ́n láǹfààní láti sin Jèhófà, àmọ́ ohun tí wọ́n ṣe fi hàn pé wọn ò yẹ lẹ́ni tó máa gbé ayé nínú Párádísè.—Mát. 25:46; 2 Tẹs. 1:9; Ìfi. 17:8; 20:15. w22.05 18 ¶16-17
Wednesday, March 6
Ọ̀dọ̀ ta la máa lọ? Ìwọ lo ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 6:68.
Jésù ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti kó àwọn èèyàn jọ sínú ètò Ọlọ́run kí wọ́n lè máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó mọ́. (Mát. 24:45) Ṣé inú ẹ ń dùn pé o wà nínú ètò náà? Èsì rẹ lè dà bí ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ fún Jésù nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Kí ni ò bá ti ṣẹlẹ̀ sí wa ká sọ pé a ò sí nínú ètò Ọlọ́run? Ètò yìí ni Kristi ń lò láti máa pèsè ohun tá a nílò ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Jésù tún máa ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè túbọ̀ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbé “ìwà tuntun” wọ̀, ìyẹn sì ń jẹ́ kí inú Jèhófà dùn sí wa. (Éfé. 4:24) Jésù ń lo ẹrú olóòótọ́ àti olóye láti máa tọ́ wa sọ́nà lákòókò wàhálà. Bí Jésù ṣe ń tọ́ wa sọ́nà máa ń ṣe wá láǹfààní. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe nígbà yẹn, àmọ́ Jésù rí i pé a rí ìtọ́sọ́nà gbà, ìyẹn sì dáàbò bò wá. w22.07 12 ¶13-14
Thursday, March 7
Ẹ . . . máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.—Fílí. 1:10.
Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa òun déédéé. (Diu. 6:6, 7) Àwọn òbí yẹn láǹfààní látàárọ̀ ṣúlẹ̀ láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì kọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkàn wá. Bí àpẹẹrẹ, ọmọdékùnrin kan lè máa bá bàbá ẹ̀ gbin nǹkan lóko tàbí kó bá a kó ohun tí wọ́n kórè wálé. Àbúrò ẹ̀ obìnrin lè ran ìyá wọn lọ́wọ́ láti ránṣọ, láti hun nǹkan tàbí láti ṣe àwọn iṣẹ́ ilé míì. Bí àwọn òbí àtàwọn ọmọ ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, wọ́n á láǹfààní láti jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè jọ sọ̀rọ̀ nípa oore Jèhófà àti bó ṣe ń ran ìdílé wọn lọ́wọ́. Ayé ti yàtọ̀ sí ti àtijọ́. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, kì í ṣeé ṣe fáwọn òbí àtàwọn ọmọ láti ráyè wà pa pọ̀ nílé. Àwọn òbí máa wà níbi iṣẹ́, àwọn ọmọ sì máa wà nílé ìwé. Torí náà, àwọn òbí gbọ́dọ̀ wáyè láti máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀.—Éfé. 5:15, 16. w22.05 28 ¶10-11
Friday, March 8
Ẹ ò mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run ni?—1 Kọ́r. 6:9.
Tí Kristẹni kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, ó ti tẹ òfin Ọlọ́run lójú. Torí náà, ó gbọ́dọ̀ gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí ji òun, kó sì sọ fún àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ ẹ̀. (Sm. 32:5; Jém. 5:14) Kí làwọn alàgbà máa wá ṣe? Jèhófà nìkan ló lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá pátápátá, ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ló sì mú kí ìyẹn ṣeé ṣe. Síbẹ̀, Jèhófà ti yan àwọn alàgbà pé kí wọ́n máa lo Ìwé Mímọ́ láti pinnu bóyá kí wọ́n yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan kúrò nínú ìjọ tàbí kí wọ́n má ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́r. 5:12) Kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ náà yanjú, ó yẹ kí wọ́n bi ara wọn láwọn ìbéèrè yìí: Ṣé ẹni náà mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ náà ni? Ṣé kì í ṣe pé ó ń bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀? Ṣé ó ti pẹ́ tó ti ń dá ẹ̀ṣẹ̀ náà? Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ṣé ẹ̀rí wà pé ó ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn? Ṣé ẹ̀rí wà tó fi hàn pé Jèhófà ti dárí ji ẹni náà?—Ìṣe 3:19. w22.06 9 ¶4
Saturday, March 9
Nífẹ̀ẹ́ òtítọ́.—Sek. 8:19.
Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa wá òdodo. (Mát. 5:6) Ìyẹn ni pé ó gbọ́dọ̀ máa wù wá láti ṣe ohun tó tọ́, ká máa ṣe rere, ká sì jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run. Ṣé o nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo? Ó dá wa lójú pé bẹ́ẹ̀ ni. O tún kórìíra irọ́ àti gbogbo ìwà burúkú. (Sm. 119:128, 163) Ṣe lẹni tó ń parọ́ ń fara wé Sátánì tó ń ṣàkóso ayé yìí. (Jòh. 8:44; 12:31) Ọ̀kan lára ohun tí Sátánì fẹ́ ṣe ni pé ó fẹ́ ba orúkọ mímọ́ Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́. Àtìgbà tí Ádámù àti Éfà ti ṣọ̀tẹ̀ ní Édẹ́nì ni Sátánì ti ń parọ́ mọ́ Jèhófà. Ó sọ pé aláìṣòótọ́ ni Jèhófà àti pé Alákòóso tó mọ tara ẹ̀ nìkan, tó sì máa ń fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn dù wọ́n ni. (Jẹ́n. 3:1, 4, 5) Irọ́ tí Sátánì pa mọ́ Jèhófà yìí ti jẹ́ káwọn èèyàn kórìíra Jèhófà. Torí náà, Sátánì máa ń mú káwọn tí ò “nífẹ̀ẹ́ òtítọ́” hùwà àìṣòótọ́ àti ìwà ìkà.—Róòmù 1:25-31. w23.03 2 ¶3
Sunday, March 10
Ìfẹ́ [Jèhófà] tí kì í yẹ̀ wà títí láé.—Sm. 100:5.
Bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kó o lè jáwọ́ nínú ìwà tí ò dáa, o tún lè rí i pé ò ń hùwà náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. O sì lè rò pé o ò ní sùúrù tó, kí gbogbo nǹkan sì tojú sú ẹ torí pé ọwọ́ ẹ ò tíì tẹ ohun tó ò ń wá. Kí lohun pàtàkì tó máa jẹ́ kó o fara dà á? Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ni. Ó dáa gan-an bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kódà kò sóhun tó dáa jùyẹn lọ. (Òwe 3:3-6) Ìfẹ́ tó lágbára tó o ní fún Jèhófà máa jẹ́ kó o borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá ẹ. Bíbélì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà máa ń fi hàn sáwa ìránṣẹ́ ẹ̀. Ìyẹn ni pé kì í pa àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ tì, ìfẹ́ tó ní sí wa kì í sì í ṣá. Jèhófà dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́n. 1:26) Torí náà, báwo la ṣe lè ní irú ìfẹ́ tí Jèhófà ní yìí? Máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. (1 Tẹs. 5:18) Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan máa bi ara ẹ pé, ‘Kí ni Jèhófà ṣe fún mi tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ mi?’ Lẹ́yìn náà, rí i dájú pé o dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó o bá ń gbàdúrà, kó o sì sọ àwọn ohun tó ti ṣe fún ẹ. Mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ ló ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe fún ẹ. w23.03 12 ¶17-19
Monday, March 11
[Jésù] mọ ohun tó wà nínú èèyàn.—Jòh. 2:25.
Sùúrù ni Jésù fi tọ́ àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ méjìlá (12) sọ́nà, kò sì bínú sí wọn. Kí la rí kọ́? Lóòótọ́, àwọn èèyàn lè ṣe ohun tí ò dáa, àmọ́ kò yẹ ká gbaná jẹ nítorí àṣìṣe wọn. Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣe ohun tó múnú bí wa, ó yẹ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí: ‘Kí nìdí tí ohun tó ṣe yẹn fi múnú bí mi gan-an? Ṣé kì í ṣe pé mo ní ìwà kan tó yẹ kí n ṣàtúnṣe ẹ̀? Ṣé kì í ṣe pé ẹni tó múnú bí mi ní ìṣòro kan tó ń bá yí? Tí ohun tó ṣe yẹn bá múnú bí mi lóòótọ́, ṣé mo lè gbójú fo àṣìṣe ẹ̀, kí n dárí jì í, kí n sì fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀?’ Torí náà, tá a bá túbọ̀ ń fìfẹ́ hàn síra wa, ìyẹn á fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ ni wá. Jésù tún kọ́ wa pé ó yẹ ká mọ ìṣòro táwọn Kristẹni bíi tiwa ní. (Òwe 20:5) Lóòótọ́, Jésù máa ń mọ ohun tó wà lọ́kàn àwa èèyàn. Àmọ́ àwa ò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, a lè ní sùúrù fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n bá ṣe ohun tó dùn wá. (Éfé. 4:1, 2; 1 Pét. 3:8) Ó máa rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá túbọ̀ sún mọ́ wọn, tá a sì mọ̀ wọ́n dáadáa. w23.03 30 ¶14-16
Tuesday, March 12
Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, àmọ́ ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn alààyè.—Lúùkù 20:38.
Sátánì máa ń lo àìsàn tó lè la ikú lọ láti mú ká ṣe ohun tí inú Jèhófà ò dùn sí. Àwọn dókítà tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè fúngun mọ́ wa pé ká gba ẹ̀jẹ̀, ìyẹn sì máa ta ko òfin Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ẹnì kan lè sọ fún wa pé ká gba ìtọ́jú tó lòdì sí ohun tí Bíbélì sọ. Òótọ́ ni pé a ò fẹ́ kú, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Jèhófà á ṣì máa nífẹ̀ẹ́ wa tá a bá tiẹ̀ kú. (Róòmù 8:37-39) Táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá kú, ó ṣì máa ń rántí wọn bíi pé wọ́n wà láàyè. (Lúùkù 20:37) Ó ń fojú sọ́nà fún ìgbà tó máa jí wọn dìde. (Jóòbù 14:15) Nǹkan ńlá ni Jèhófà san ká “lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) A mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ń bójú tó wa. Torí náà, dípò ká pa òfin Jèhófà tì nígbà tá a bá ṣàìsàn tó lè gbẹ̀mí wa tàbí nígbà táwọn kan bá halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn máa pa wá, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó tù wá nínú, kó sì fún wa lọ́gbọ́n àti okun tá a nílò.—Sm. 41:3. w22.06 18 ¶16-17
Wednesday, March 13
Ọgbọ́n tòótọ́ ń ké jáde ní ojú ọ̀nà.—Òwe 1:20.
Bíbélì sọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni òye.” (Òwe 9:10) Torí náà, tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì, ó yẹ ká lo ìmọ̀ Jèhófà, ìyẹn “ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ” láti ṣe ìpinnu náà. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ka Bíbélì tá a sì ń ṣèwádìí nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé a ní ọgbọ́n tòótọ́. (Òwe 2:5-7) Jèhófà nìkan ló lè fún wa ní ọgbọ́n tòótọ́. (Róòmù 16:27) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé òun ni Orísun ọgbọ́n? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ó sì ní ìmọ̀ àti òye nípa gbogbo nǹkan tó dá. (Sm. 104:24) Ìkejì, gbogbo nǹkan tí Jèhófà ń ṣe ló fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni. (Róòmù 11:33) Ìkẹta, gbogbo àwọn tó bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Jèhófà ń fún wa máa ń jàǹfààní. (Òwe 2:10-12) Torí náà, tá a bá fẹ́ ní ọgbọ́n tòótọ́, a gbọ́dọ̀ gbà pé òótọ́ làwọn nǹkan mẹ́ta tá a sọ yẹn, ká sì jẹ́ kí wọ́n máa darí wa tá a bá fẹ́ ṣèpinnu. w22.10 19 ¶3-4
Thursday, March 14
Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jà, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jà, àmọ́ wọn ò borí, kò sì sí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run.—Ìfi. 12:7, 8.
Sátánì fìdí rẹmi nínú ogun tí Ìfihàn orí 12 sọ, Jésù sì ju òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù sí ayé. Inú wá ń bí Èṣù gan-an, ó ń fi ìkanra mọ́ gbogbo aráyé, ìyẹn ló sì mú kí wàhálà pọ̀ láyé. (Ìfi. 12:9-12) Àǹfààní wo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣe wá? Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti bí ìwà àwọn èèyàn ṣe ń burú sí i jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ti di Ọba. Torí náà, kò yẹ ká máa bínú táwọn èèyàn bá ń hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan, tí wọ́n sì ń hùwà ìkà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa rántí pé ìwà wọn ń fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ. Ẹ ò rí i pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso! (Sm. 37:1) Ó sì dájú pé ṣe ni nǹkan á máa burú sí i bí Amágẹ́dọ́nì ṣe ń sún mọ́lé. (Máàkù 13:8; 2 Tím. 3:13) Ṣé kò yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa pé ó jẹ́ ká mọ ìdí táwọn nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀ lásìkò wa yìí? w22.07 3-4 ¶7-8
Friday, March 15
Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo lágbára gan-an.—Jém. 5:16.
A lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ káwọn ará wa fara da àìsàn, àjálù, ogun, inúnibíni àtàwọn ìṣòro míì. Ó tún yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá. Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan tó nírú àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu bà yìí. O ò ṣe dárúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nínú àdúrà ẹ? Tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí wọ́n fara dà á, ìyẹn fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. Àwọn tó ń ṣàbójútó wa nínú ìjọ máa ń mọyì ẹ̀ gan-an tá a bá gbàdúrà fún wọn, ó sì máa ń ṣe wọ́n láǹfààní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà jẹ́ ká mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Ẹ máa gbàdúrà fún èmi náà, kí a lè fún mi lọ́rọ̀ sọ tí mo bá la ẹnu mi, kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nígbà tí mo bá ń sọ àṣírí mímọ́ ìhìn rere.” (Éfé. 6:19) Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ arákùnrin ló wà nínú ètò Ọlọ́run tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára, tí wọ́n sì ń ṣàbójútó wa. A máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wọ́n lọ́wọ́. w22.07 23-24 ¶14-16
Saturday, March 16
Ẹ . . . dé ìrètí ìgbàlà bí akoto.—1 Tẹs. 5:8.
Àwọn sójà máa ń wọ akoto kó lè dáàbò bo orí wọn. Lọ́nà kan náà, bá a ṣe ń bá Sátánì jà, a gbọ́dọ̀ dáàbò bo ọkàn wa ká má bàa ro èròkerò. Ó máa ń fi oríṣiríṣi nǹkan dán wa wò, ká lè máa ro èròkerò. Bí akoto ṣe máa ń dáàbò bo orí sójà kan, bẹ́ẹ̀ náà ni ìrètí tá a ní máa ń dáàbò bo ọkàn wa ká má bàa ro èròkerò, ká sì lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Àmọ́ tí ìrètí tá a ní ò bá dá wa lójú mọ́, tá a wá jẹ́ kí èròkerò gbà wá lọ́kàn, ó lè má jẹ́ ká nírètí mọ́ pé a máa wà láàyè títí láé. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni kan nílùú Kọ́ríńtì àtijọ́. Ìgbà kan wà tí wọn ò nígbàgbọ́ mọ́ nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe pé àwọn òkú máa jíǹde. (1 Kọ́r. 15:12) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tí ò gbà pé àjíǹde wà máa ń ṣe ohun tó wù wọ́n torí wọn ò nírètí kankan pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. (1 Kọ́r. 15:32) Bákan náà lónìí, àwọn tí ò gba ìlérí tí Ọlọ́run ṣe gbọ́ ń ṣe ohun tó wù wọ́n, wọ́n ń jayé òní torí wọ́n gbà pé àwọn ò mẹ̀yìn ọ̀la. Àmọ́ àwa yàtọ̀ sí wọn torí a nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe. w22.10 25-26 ¶8-9
Sunday, March 17
Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo.—1 Tẹs. 5:17.
Jèhófà fẹ́ kó o máa gbàdúrà sóun. Ó mọ àwọn ìṣòro tó ò ń dojú kọ, ó sì fi dá ẹ lójú pé gbogbo ìgbà lòun ṣe tán láti gbọ́ àdúrà ẹ. Inú Jèhófà máa ń dùn láti gbọ́ àdúrà táwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ ń gbà sí i. (Òwe 15:8) Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà, kí lo lè sọ nínú àdúrà ẹ? Sọ gbogbo bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà. (Sm. 62:8) Sọ gbogbo ìṣòro ẹ fún un àti báwọn ìṣòro náà ṣe ń kó ẹ lọ́kàn sókè. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da àwọn ìṣòro tó ò ń bá yí, kó sì jẹ́ kó o lè fìgboyà sọ̀rọ̀. O lè bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n tí wàá fi ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ lọ́nà tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn. (Lúùkù 21:14, 15) Tó o bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí nǹkan tojú sú ẹ, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè sọ̀rọ̀ náà fún Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. O tún lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ẹni tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ náà fún fara balẹ̀ gbọ́ ẹ dáadáa kó lè mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Máa kíyè sí bó ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà ẹ, kó o sì jẹ́ káwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wàá rí i pé kò ní ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà mọ́. w22.08 10 ¶6
Monday, March 18
Àwọn ọkùnrin yìí ló ń ta ko àwọn àṣẹ Késárì.—Ìṣe 17:7.
Lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ tó wà ní Tẹsalóníkà sílẹ̀, àwọn ará dojú kọ inúnibíni tó le gan-an. Àwọn alátakò kan tí inú ń bí burúkú burúkú wọ́ “àwọn arákùnrin kan lọ sọ́dọ̀ àwọn alákòóso ìlú.” (Ìṣe 17:6) Ṣé ẹ rò pé ẹ̀rù ò ní máa ba àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni yẹn? Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí lè mú kí wọ́n dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àmọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀. Ó rí i dájú pé àwọn bójú tó àwọn ará tó wà ní ìjọ tuntun náà dáadáa. Pọ́ọ̀lù rán àwọn ará Tẹsalóníkà létí pé: ‘A rán Tímótì, arákùnrin wa kí ó lè mú kí ẹ fìdí múlẹ̀, kí ó sì tù yín nínú nítorí ìgbàgbọ́ yín, kí àwọn ìpọ́njú yìí má bàa mú ẹnì kankan yẹsẹ̀.’ (1 Tẹs. 3:2, 3) Tímótì ti rí bí Pọ́ọ̀lù ṣe fún àwọn ará níṣìírí ní Lísírà kí wọ́n lè lókun. Tímótì rí bí Jèhófà ṣe dáàbò bò wọ́n, ìyẹn ló jẹ́ kó fi dá àwọn ará Tẹsalóníkà lójú pé Jèhófà máa wà pẹ̀lú àwọn náà.—Ìṣe 14:8, 19-22; Héb. 12:2. w22.08 21 ¶4
Tuesday, March 19
A ní ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.—1 Jòh. 4:9.
Lọ́dún 1870, àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí Charles Taze Russell jẹ́ alábòójútó wọn bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀. Wọ́n fẹ́ mọ̀ nípa ìdí tí Jésù ṣe fi ara ẹ̀ rúbọ àti bó ṣe yẹ ká máa ṣe Ìrántí Ikú ẹ̀. Lónìí, à ń jàǹfààní ìwádìí tí wọ́n ṣe nínú Bíbélì kí wọ́n lè mọ òtítọ́. Lọ́nà wo? A ti mọ òtítọ́ nípa bí Jésù ṣe fi ara ẹ̀ rúbọ àti àǹfààní tó ṣe gbogbo aráyé. (1 Jòh. 2:1, 2) A tún ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì pé àwùjọ èèyàn méjì tó ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run ló máa rí ojú rere rẹ̀. Àwùjọ àkọ́kọ́ ni àwọn tó nírètí láti gbé lọ́run, wọn ò sì ní kú mọ́. Àwùjọ kejì ni àwọn èèyàn tó nírètí láti gbé ayé títí láé. Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, tá à ń rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, tá a sì tún rí i pé ẹbọ ìràpadà Jésù ń ṣe wá láǹfààní ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (1 Pét. 3:18) Torí náà, bíi tàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, a máa ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi, ká lè ṣe é bó ṣe ní ká máa ṣe é. w23.01 21 ¶6-7
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 9) Máàkù 14:3-9
Wednesday, March 20
Ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.—2 Kọ́r. 5:15.
Jésù kọ́ àwọn èèyàn nípa àwọn ohun rere tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé. A mọyì ìràpadà torí ó jẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà àti Jésù. Gbogbo àwọn tó bá gba Jésù gbọ́ tún nírètí láti gbé ayé títí láé, wọ́n sì máa rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú. (Jòh. 5:28, 29; Róòmù 6:23) Ká sòótọ́, àwọn ohun rere tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún wa yìí ò tọ́ sí wa, kò sì sóhun tá a lè fi san oore tí Ọlọ́run àti Kristi ṣe fún wa pa dà. (Róòmù 5:8, 20, 21) Àmọ́, a lè fi hàn pé a moore. Báwo la ṣe máa ṣe é? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń lo gbogbo ohun tá a ní láti fi ti iṣẹ́ Jèhófà lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, a lè yọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn ilé tá a ti ń jọ́sìn Jèhófà àti nígbà tí wọ́n bá ń tún wọn ṣe. w23.01 26 ¶3; 28 ¶5
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 9) Máàkù 11:1-11
Thursday, March 21
Mo rí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà . . . àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) sì wà pẹ̀lú rẹ̀.—Ìfi. 14:1.
Gbogbo orílẹ̀-èdè ayé làwọn tó máa ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run máa bójú tó. Bíi ti Jésù, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì máa jẹ́ ọba àti àlùfáà. (Ìfi. 5:10) Nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Òfin tí Ọlọ́run fún Mósè sọ pé àwọn àlùfáà ni kó máa bójú tó ètò ìlera àwọn èèyàn, kí wọ́n sì rí i dájú pé àwọn èèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Nítorí pé Òfin náà ni “òjìji àwọn nǹkan rere tó ń bọ̀,” ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé àwọn tó máa bá Jésù ṣàkóso máa ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìlera pípé àti àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. (Héb. 10:1) A ò tíì mọ bí àwọn ọba àtàwọn àlùfáà yìí ṣe máa bá àwọn èèyàn tó wà láyé sọ̀rọ̀ nínú Ìjọba Ọlọ́run, ó dìgbà yẹn ká tó mọ̀. Àmọ́, ó dá wa lójú pé nínú Párádísè, àwọn tó wà láyé máa rí ìtọ́sọ́nà gbà.—Ìfi. 21:3, 4. w22.12 11 ¶11-13
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 10) Máàkù 11:12-19
Friday, March 22
Ẹ̀ ń kéde ikú Olúwa, títí á fi dé.—1 Kọ́r. 11:26.
Ọ̀kan lára ìdí tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi ni pé a fẹ́ káwọn tó wá fúngbà àkọ́kọ́ mọ ohun tí Jèhófà àti Jésù ti ṣe fún aráyé. (Jòh. 3:16) A retí pé ohun tí wọ́n rí tí wọ́n sì gbọ́ níbẹ̀ máa mú kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọ́n sì di ìránṣẹ́ rẹ̀. A tún máa ń pe àwọn tó ń sin Jèhófà tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí wọn ò sìn ín mọ́ wá síbi ìpàdé pàtàkì yìí. Ìdí tá a fi ń pè wọ́n ni pé a fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń wá, inú wa sì máa ń dùn láti rí wọn. Ìrántí Ikú Kristi máa ń rán wọn létí ayọ̀ tí wọ́n máa ń ní nígbà tí wọ́n ṣì ń sin Jèhófà. (Sm. 103:1-4) Torí náà, bóyá àwọn èèyàn tá a pè wá tàbí wọn ò wá, a ṣì máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pè wọ́n wá sí Ìrántí Ikú Kristi torí a mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà ni ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wá síbẹ̀.—Lúùkù 15:7; 1 Tím. 2:3, 4. w23.01 20 ¶1; 22-23 ¶9-11
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 11) Máàkù 11:20–12:27, 41-44
Saturday, March 23
Ojú Jèhófà ń ṣọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.—Sm. 33:18.
Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run pé kó ṣohun kan fún òun. Ó bẹ Jèhófà pé kó máa ṣọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn òun. (Jòh. 17:15, 20) Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì máa ń bójú tó wọn. Àmọ́, Jésù mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa dojú kọ àtakò tó le gan-an látọ̀dọ̀ Sátánì. Jésù tún mọ̀ pé kí wọ́n tó lè borí àtakò látọ̀dọ̀ Èṣù, àfi kí Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ìṣòro làwa Kristẹni tòótọ́ ń dojú kọ lónìí torí inú ayé burúkú tí Sátánì ń darí là ń gbé. A máa ń láwọn ìṣòro tó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, tó sì máa ń dán ìgbàgbọ́ wa wò. Àmọ́, kò yẹ ká bẹ̀rù rárá. Jèhófà ń rí gbogbo ìṣòro tá à ń dojú kọ, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn ìṣòro náà. Jèhófà máa “ń ṣọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ . . . láti gbà wọ́n.”—Sm. 33:18-20. w22.08 8 ¶1-2
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 12) Máàkù 14:1, 2, 10, 11; Mátíù 26:1-5, 14-16
ỌJỌ́ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
Lẹ́yìn Tí Oòrùn Bá Wọ̀
Sunday, March 24
Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.—Lúùkù 22:19.
Lọ́dọọdún, láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi àtàwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, a máa ń gbàdúrà, a sì máa ń ronú dáadáa nípa ìdí tí Jésù fi kú, ká lè fi hàn pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń pe ọ̀pọ̀ èèyàn pé kí wọ́n wá dara pọ̀ mọ́ wa níbi ìpàdé pàtàkì náà. Àwa fúnra wa sì máa ń rí i dájú pé ohunkóhun ò dí wa lọ́wọ́ láti wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́jọ́ náà. Níbi Ìrántí Ikú Kristi, a máa ń mọ ìdí tí aráyé fi nílò ìràpadà àti bí ikú ọkùnrin kan ṣoṣo ṣe gba ọ̀pọ̀ èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. A tún máa ń rán wa létí ohun tí búrẹ́dì àti wáìnì tá a máa ń lò níbi Ìrántí Ikú Kristi ṣàpẹẹrẹ àtàwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ, kí wọ́n sì mu nínú rẹ̀. (Lúùkù 22:19, 20) Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń ronú nípa àwọn ohun rere tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe fáwọn tó nírètí láti gbé ayé. (Àìsá. 35:5, 6; 65:17, 21-23) Òótọ́ làwọn nǹkan tá à ń gbọ́ níbi àsọyé yẹn, kò sì yẹ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú wọn. w23.01 20 ¶2; 21 ¶4
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 13) Máàkù 14:12-16; Mátíù 26:17-19 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 14) Máàkù 14:17-72
Monday, March 25
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 3:16.
Jèhófà jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ kú kó lè rà wá pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa, ìyẹn ló jẹ́ ká nírètí pé a máa wà láàyè títí láé. (Mát. 20:28) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí ikú ṣe wá nípasẹ̀ ẹnì kan, àjíǹde òkú náà wá nípasẹ̀ ẹnì kan. Nítorí bí gbogbo èèyàn ṣe ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ gbogbo èèyàn di ààyè nínú Kristi.” (1 Kọ́r. 15:21, 22) Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé àti pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ayé. (Mát. 6:9, 10) Ara ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fáwa èèyàn ni pé ká máa gbé ayé títí láé. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, Jèhófà ti yan Ọmọ ẹ̀ láti jẹ́ Ọba Ìjọba náà. Ọlọ́run sì ti ń kó àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) jọ lára àwa tá a wà láyé, kí wọ́n lè bá Jésù ṣàkóso láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ.—Ìfi. 5:9, 10. w22.12 5 ¶11-12
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 14) Máàkù 15:1-47
Tuesday, March 26
Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di dandan fún wa . . . kí àwọn tó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́.—2 Kọ́r. 5:14, 15.
Tí èèyàn wa kan bá kú, àárò ẹ̀ máa ń sọ wá gan-an! Ó máa ń dùn wá pàápàá tó bá jẹ̀rora kó tó kú. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a máa ń pa dà láyọ̀ tá a bá ń rántí ohun tẹ́ni náà kọ́ wa, bó ṣe fún wa níṣìírí tàbí ohun tó sọ tó pa wá lẹ́rìn-ín. Lọ́nà kan náà, ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá wa gan-an tá a bá kà nípa bí Jésù ṣe jìyà tó sì kú. Nígbà Ìrántí Ikú Kristi, a sábà máa ń ronú nípa ìdí tí Jésù ṣe fi ara ẹ̀ rúbọ. (1 Kọ́r. 11:24, 25) Àmọ́, a tún máa ń láyọ̀ gan-an tá a bá ronú nípa àwọn nǹkan tí Jésù sọ àtohun tó ṣe nígbà tó wà láyé. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jésù ń ṣe báyìí àtàwọn nǹkan tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú, ó máa ń mórí wa wú. w23.01 26 ¶1-2
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 15) Mátíù 27:62-66 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 16) Máàkù 16:1
Wednesday, March 27
Ẹ máa wá Ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́.—Mát. 6:33.
Nígbà tí Jésù kú, inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bà jẹ́ gan-an. Yàtọ̀ sí pé ọ̀rẹ́ wọn ti kú, ṣe ló tún ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò nírètí mọ́. (Lúùkù 24:17-21) Àmọ́ nígbà tí Jésù fara hàn wọ́n, ó fara balẹ̀ ṣàlàyé ìdí tóun fi gbọ́dọ̀ jìyà kóun sì kú àti báwọn nǹkan yẹn ṣe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún wọn. (Lúùkù 24:26, 27, 45-48) Nígbà tí Jésù fi máa pa dà sọ́run, ẹkún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ti dayọ̀. Ìdí sì ni pé wọ́n mọ̀ pé Ọ̀gá àwọn ti jíǹde, ó sì máa ran àwọn lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ náà yanjú. Torí náà, ayọ̀ tí wọ́n ní yìí ń jẹ́ kí wọ́n yin Jèhófà, wọn ò sì jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù sú wọn. (Lúùkù 24:52, 53; Ìṣe 5:42) Ká lè fara wé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ó máa gba pé ká fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. Lóòótọ́, ó yẹ ká ní ìfaradà ká tó lè máa sin Jèhófà nìṣó, àmọ́ Jèhófà ti ṣèlérí fún wa pé òun máa bù kún wa gan-an tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀.—Òwe 10:22. w23.01 30-31 ¶15-16
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 16) Máàkù 16:2-8
Thursday, March 28
Ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.—Jẹ́n. 3:19.
A ò ní fẹ́ ṣe àṣìṣe tí Ádámù àti Éfà ṣe. Tá ò bá fẹ́ kí irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ká mọyì àwọn ànímọ́ rẹ̀, ká sì máa ronú lọ́nà tó ń gbà ronú. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á túbọ̀ máa lágbára sí i. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Ábúráhámù yẹ̀ wò. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé láwọn ìgbà kan, ó ṣòro fún un láti mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣe àwọn ìpinnu kan, Ábúráhámù ò torí ìyẹn kẹ̀yìn sí Jèhófà. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló gbìyànjú láti túbọ̀ mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó gbọ́ pé Jèhófà fẹ́ pa Sódómù àti Gòmórà run, Ábúráhámù kọ́kọ́ rò pé “Onídàájọ́ gbogbo ayé” máa pa àwọn èèyàn burúkú pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olódodo. Ábúráhámù gbà pé Jèhófà ò ní ṣe irú ẹ̀ láé, torí náà ó fìrẹ̀lẹ̀ bi Jèhófà láwọn ìbéèrè kan, Jèhófà náà sì fi sùúrù dá a lóhùn. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Ábúráhámù rí i pé Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn gbogbo àwa èèyàn, kì í sì í fìyà jẹ àwọn aláìṣẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.—Jẹ́n. 18:20-32. w22.08 28 ¶9-10
Friday, March 29
Ẹni tó ṣeé fọkàn tán máa ń pa àṣírí mọ́.—Òwe 11:13.
Lọ́dún 455 Ṣ.S.K., lẹ́yìn tí Gómìnà Nehemáyà tún àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́, ó wá àwọn ọkùnrin tó ṣeé fọkàn tán kí wọ́n lè máa bójú tó ìlú náà. Nehemáyà wá yan Hananáyà lára àwọn ọkùnrin náà pé kó jẹ́ olórí Ibi Ààbò. Bíbélì sọ pé Hananáyà ló “ṣeé fọkàn tán jù lọ, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ ju ọ̀pọ̀ àwọn míì lọ.” (Neh. 7:2) Hananáyà fọwọ́ pàtàkì mú gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò sì fẹ́ ṣe ohun tí inú ẹ̀ ò dùn sí. Táwa náà bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tá ò sì ṣe ohun tó máa bà á nínú jẹ́, àwọn èèyàn máa fọkàn tán wa nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run tá à ń ṣe. Àpẹẹrẹ ẹlòmíì ni Tíkíkù. Òun àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jọ ṣiṣẹ́, Pọ́ọ̀lù sì fọkàn tán an. Tíkíkù máa ń ràn án lọ́wọ́ torí Pọ́ọ̀lù pè é ní “òjíṣẹ́ olóòótọ́.” (Éfé. 6:21, 22) Pọ́ọ̀lù fọkàn tán an pé kì í ṣe pé ó kàn máa fi àwọn lẹ́tà òun jíṣẹ́ fáwọn ará ní Éfésù àti Kólósè nìkan, ó tún máa gbà wọ́n níyànjú, á sì tù wọ́n nínú. Àpẹẹrẹ Tíkíkù jẹ́ ká rántí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tó ṣeé fọkàn tán, tí wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí láti sún mọ́ Jèhófà.—Kól. 4:7-9. w22.09 9-10 ¶5-6
Saturday, March 30
Ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.—1 Pét. 4:8.
Jósẹ́fù dojú kọ àwọn ìṣòro tó le gan-an fún nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá (13). Jósẹ́fù tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ṣé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun ṣá. Ó sì lè máa rò pé Jèhófà ti pa òun tì lásìkò tó yẹ kó ran òun lọ́wọ́. Àmọ́ Jósẹ́fù ò ronú bẹ́ẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó fara balẹ̀, ó sì ronú lọ́nà tó tọ́. Kódà, nígbà tó láǹfààní láti gbẹ̀san lára àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fìfẹ́ hàn sí wọn, tó sì dárí jì wọ́n. (Jẹ́n. 45:4, 5) Ohun tó ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ tó fi lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó ronú lọ́nà tó tọ́. Dípò kó máa ronú ṣáá nípa ohun táwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ ṣe sí i, ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe ló gbájú mọ́. (Jẹ́n. 50:19-21) Kí la rí kọ́? Tí wọ́n bá ṣe nǹkan tí ò dáa sí ẹ, má bínú sí Jèhófà tàbí kó o máa rò pé Jèhófà ti pa ẹ́ tì. Máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro náà. Yàtọ̀ síyẹn, táwọn èèyàn bá ṣe ohun tí ò dáa sí ẹ, má wo àìpé wọn, ṣe ni kó o máa fìfẹ́ hàn sí wọn. w22.11 21 ¶4
Sunday, March 31
Gbogbo ìjọba á máa sìn wọ́n, wọ́n á sì máa ṣègbọràn sí wọn.—Dán. 7:27.
Wòlíì Dáníẹ́lì rí àwọn ìran kan tó jẹ́ ká rí i kedere pé Jèhófà láṣẹ ju gbogbo àwọn aláṣẹ ayé lọ. Dáníẹ́lì kọ́kọ́ rí ẹranko ńlá mẹ́rin tó ṣàpẹẹrẹ àwọn ìjọba tó ti ṣàkóso ayé kọjá, ìyẹn Bábílónì, Mídíà àti Páṣíà, Gíríìsì, Róòmù, ó tún rí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó jáde látinú ìjọba Róòmù, òun ló sì ń ṣàkóso ayé báyìí. (Dán. 7:1-3, 17) Lẹ́yìn náà, Dáníẹ́lì rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ ní kọ́ọ̀tù lọ́run. (Dán. 7:9, 10) Ọlọ́run gba agbára àti àṣẹ kúrò lọ́wọ́ àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso, ó sì gbé e fún àwọn míì tó lágbára, tó sì dáa jù wọ́n lọ. Àwọn wo ló gbé e fún? Ó gbé e fún “ẹnì kan bí ọmọ èèyàn,” ìyẹn Jésù Kristi àti àwọn “ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ,” ìyẹn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó máa ṣàkóso “títí láé àti láéláé.” (Dán. 7:13, 14, 18) Torí náà, ó dájú pé Jèhófà ni “Onípò Àjùlọ.” Ohun tí Dáníẹ́lì rí nínú ìran bá ohun tó sọ ṣáájú ìgbà yẹn mu. Dáníẹ́lì sọ pé: “Ọlọ́run ọ̀run . . . ń mú ọba kúrò, ó sì ń fi ọba jẹ.”—Dán. 2:19-21. w22.10 14-15 ¶9-11