April
Monday, April 1
Ìgbàgbọ́ yín tí a dán wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó máa mú kí ẹ ní ìfaradà.—Jém. 1:3.
Bi ara ẹ pé: ‘Kí ni mo máa ń ṣe tí wọ́n bá bá mi wí? Ṣé mo máa ń tètè gbà pé mo ṣàṣìṣe àbí ṣe ni mo máa ń dá ara mi láre? Ṣé mi ò kì í dá àwọn èèyàn lẹ́bi tí mo bá ṣàṣìṣe?’ Tó o bá ń kà nípa àwọn ọkùnrin àtobìnrin olóòótọ́ tó wà nínú Bíbélì, o lè wo ohun tí wọ́n ṣe kí wọ́n má bàa kó síṣòro. Bó o ṣe ń kà nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, bi ara ẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ bíi ti ìránṣẹ́ Jèhófà yìí?’ A máa jàǹfààní gan-an tá a bá ń kíyè sí àwọn àgbàlagbà àtàwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ wa. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o mọ ẹnì kan nínú ìjọ yín tó ń fara da ìṣòro kan, bíi káwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ máa fúngun mọ́ ọn pé kó ṣe ohun tí ò dáa, káwọn ìdílé ẹ̀ máa ṣenúnibíni sí i tàbí kó máa ṣàìsàn? Ṣé o kíyè sí ìwà kan tó dáa lára ẹni náà tíwọ náà máa fẹ́ ní? Tó o bá ń ronú nípa àpẹẹrẹ tó dáa tí ẹni náà fi lélẹ̀, ó máa rọrùn fún ẹ láti fara da àwọn ìṣòro tó o ní. Inú wa dùn gan-an pé a láwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó nígbàgbọ́ tá a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn lónìí!—Héb. 13:7. w22.04 13 ¶13-14
Tuesday, April 2
Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.—Ìṣe 20:35.
Tá a bá dojú kọ ìṣòro kan nígbèésí ayé wa, inú wa máa dùn tí alàgbà kan bá tẹ́tí sí wa, tó sì tù wá nínú. Tá a bá fẹ́ kẹ́nì kan ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́, inú wa máa dùn tí aṣáájú-ọ̀nà kan bá tẹ̀ lé wa lọ, tó sì fún wa nímọ̀ràn tó máa ran ẹni náà lọ́wọ́. Inú gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí máa ń dùn láti ràn wá lọ́wọ́, ó sì yẹ káwa náà yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ kínú tiwọn náà lè dùn. Tíwọ náà bá fẹ́ máa ran àwọn ará lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà yìí tàbí láwọn ọ̀nà míì, kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Má kàn sọ pé o fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i, ní ohun kan pàtó lọ́kàn tó o fẹ́ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé, ‘Mo fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọ.’ Àmọ́, ó lè ṣòro fún ẹ láti mọ ohun tó o fẹ́ ṣe gan-an, o sì lè má mọ̀ tọ́wọ́ ẹ bá ti tẹ ohun tó ò ń wá. Torí náà, mọ nǹkan pàtó tó o fẹ́ ṣe. Kódà, o lè kọ ohun tó o fẹ́ ṣe sílẹ̀ àti bó o ṣe máa ṣe é. w22.04 25 ¶12-13
Wednesday, April 3
Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.—Jém. 2:8.
Jèhófà ti ń kó “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” jọ báyìí, ó sì ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n láti gbé lábẹ́ Ìjọba rẹ̀. (Ìfi. 7:9, 10) Lónìí, ogun ò jẹ́ káwọn èèyàn wà níṣọ̀kan mọ́, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n máa bẹ̀rù ara wọn. Àmọ́ àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn yìí ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí, ẹ̀yà wọn tàbí irú ẹni tí wọ́n jẹ́. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n ti ń fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀ báyìí. (Míkà 4:3) Dípò tí wọ́n á fi máa jagun tó ń fẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣòfò, ṣe ni wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ àtohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé, kí wọ́n lè ní “ìyè tòótọ́.” (1 Tím. 6:19) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn mọ̀lẹ́bí wọn lè ta kò wọ́n tàbí kí wọ́n má fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ torí pé Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n fara mọ́, Jèhófà ń rí i dájú pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò ni òun ń pèsè fún wọn. (Mát. 6:25, 30-33; Lúùkù 18:29, 30) Àwọn nǹkan yìí ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa yanjú àwọn ìṣòro wa àti pé Ìjọba yìí ni Jèhófà máa lò láti ṣe àwọn nǹkan tó fẹ́ fún aráyé. w22.12 5 ¶13
Thursday, April 4
Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.—Ìfi. 22:20.
Nígbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá máa fi parí, gbogbo àwọn tó ń gbé ayé á ti di ẹni pípé. Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù ò ní mú kí ẹnikẹ́ni dẹ́ṣẹ̀ mọ́. (Róòmù 5:12) Ègún tó wà lórí aráyé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ò ní sí mọ́. Ìyẹn ló máa mú kí àwọn èèyàn tó ń gbé ayé “pa dà wà láàyè,” kí wọ́n sì di ẹni pípé níparí ẹgbẹ̀rún ọdún náà. (Ìfi. 20:5) A mọ̀ pé nígbà tí Sátánì dán Jésù wò, tó fẹ́ kó di aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run, Jésù ò gbà fún un torí ó jẹ́ olóòótọ́. Àmọ́ ṣé gbogbo àwọn ẹni pípé ló máa jẹ́ olóòótọ́ nígbà tí Jèhófà bá gba Sátánì láyè láti dán wọn wò? Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa dáhùn ìbéèrè yẹn nígbà tí wọ́n bá tú Sátánì sílẹ̀ nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ níparí ẹgbẹ̀rún ọdún náà. (Ìfi. 20:7) Àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ nígbà àdánwò ìkẹyìn yìí máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun, wọ́n á sì ní òmìnira tòótọ́ títí láé. (Róòmù 8:21) Jèhófà máa pa gbogbo àwọn tó bá ṣọ̀tẹ̀ run pátápátá.—Ìfi. 20:8-10. w22.05 19 ¶18-19
Friday, April 5
Ìwọ yóò sì ṣe é léṣe ní gìgísẹ̀.—Jẹ́n. 3:15.
Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ nígbà tí Sátánì mú kí àwọn Júù àtàwọn ará Róòmù pa Ọmọ Ọlọ́run. (Lúùkù 23:13, 20-24) Téèyàn bá ṣèṣe lẹ́sẹ̀, ó lè má jẹ́ kí ẹni náà rìn dáadáa fún ọjọ́ mélòó kan. Lọ́nà kan náà, Jésù ò lè ṣe nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ mẹ́ta tó fi wà nínú ibojì. (Mát. 16:21) Kí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15 tó lè ṣẹ, Jésù gbọ́dọ̀ jíǹde. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ, ọmọ náà máa fọ́ orí ejò yẹn. Torí náà, Jésù gbọ́dọ̀ jíǹde. Ó sì jíǹde lóòótọ́! Nígbà tó di ọjọ́ kẹta tí Jésù kú, Jèhófà jí i dìde, ó sì di ẹni ẹ̀mí tí ò lè kú mọ́. Tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, ó máa lo Jésù láti pa Sátánì run ráúráú. (Héb. 2:14) Kristi àtàwọn tó máa bá a ṣàkóso máa pa gbogbo àwọn ọ̀tá Ọlọ́run run ráúráú, ìyẹn ọmọ ejò náà.—Ìfi. 17:14; 20:4, 10. w22.07 16 ¶11-12
Saturday, April 6
Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.—Òwe 13:20.
Ẹ̀yin òbí, ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọ̀rẹ́ wa lè jẹ́ ká ṣe nǹkan tó dáa tàbí ohun tí ò dáa. Ṣé ẹ mọ ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ yín? Kí lẹ lè ṣe láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti yan àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? (1 Kọ́r. 15:33) Ẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yan àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa tẹ́ ẹ bá ń pe àwọn ará míì tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà pé kí wọ́n wá dara pọ̀ mọ́ yín nígbà ìjọsìn ìdílé tàbí nígbà tẹ́ ẹ bá fẹ́ ṣeré jáde. (Sm. 119:63) Bàbá kan tó ń jẹ́ Tony sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún lèmi àtìyàwó mi ti máa ń pe àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá sílé wa. A jọ máa ń jẹun, wọ́n sì máa ń dara pọ̀ mọ́ ìjọsìn ìdílé wa. Ọ̀nà tó dáa jù lọ nìyẹn láti mọ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń fayọ̀ sìn ín. . . . Àwọn ìrírí tí wọ́n ní, ìtara wọn àti bí wọ́n ṣe yọ̀ǹda ara wọn ti jẹ́ káwọn ọmọ wa sún mọ́ Jèhófà gan-an.” w22.05 29-30 ¶14-15
Sunday, April 7
Ohunkóhun tí ẹ bá dè ní ayé máa jẹ́ ohun tí a ti dè ní ọ̀run.—Mát. 18:18.
Tí àwọn alàgbà bá fẹ́ gbọ́ ẹjọ́ ẹnì kan tó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìpinnu tí Jèhófà ṣe lọ́run nípa ẹni náà làwọn náà ṣe. Báwo làwọn ará ìjọ ṣe máa ń jàǹfààní látinú ètò yìí? Ó máa ń jẹ́ kí wọ́n yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ kí ìwà ẹ̀ má bàa ran àwọn ará yòókù. (1 Kọ́r. 5:6, 7, 11-13; Títù 3:10, 11) Ó tún máa ń jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ronú pìwà dà, kí Jèhófà lè dárí jì í. (Lúùkù 5:32) Àwọn alàgbà máa ń gbàdúrà fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà, wọ́n sì máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ẹni náà pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. (Jém. 5:15) Ká sọ pé ẹnì kan ò ronú pìwà dà nígbà tí àwọn alàgbà gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀, ṣe ni wọ́n máa yọ ẹni náà kúrò nínú ìjọ. Àmọ́, tí ẹni náà bá ronú pìwà dà, tó sì jáwọ́ nínú ìwà burúkú náà, Jèhófà máa dárí jì í. (Lúùkù 15:17-24) Kódà tí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹni náà dá bá burú jáì, Jèhófà ṣì máa dárí jì í.—2 Kíró. 33:9, 12, 13; 1 Tím. 1:15. w22.06 9 ¶5-6
Monday, April 8
Ẹ máa ronú bó ṣe tọ́, ẹ wà lójúfò! Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá yín ń rìn káàkiri bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù, ó ń wá bó ṣe máa pani jẹ.—1 Pét. 5:8.
Ibi yòówù káwa Kristẹni wà láyé, Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tá a ní, ó sì ń jẹ́ ká borí àwọn ìdẹwò Èṣù. (1 Pét. 5:9) Ìwọ náà lè borí ìdẹwò Èṣù. Láìpẹ́, Jèhófà máa pàṣẹ fún Jésù àtàwọn tó máa bá a jọba pé kí wọ́n “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòh. 3:8) Lẹ́yìn ìyẹn, àwa tá à ń sin Jèhófà láyé “ò ní bẹ̀rù ohunkóhun, ohunkóhun ò sì ní já [wa] láyà” mọ́. (Àìsá. 54:14; Míkà 4:4) Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti borí àwọn nǹkan tó ń bà wá lẹ́rù. A gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á máa nífẹ̀ẹ́ wa, á sì máa dáàbò bò wá. Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká máa ronú lórí bí Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ nígbà àtijọ́, ká sì máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Bákan náà, ẹ jẹ́ ká máa rántí bí Ọlọ́run ṣe ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a níṣòro. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn nǹkan tó ń bà wá lẹ́rù!—Sm. 34:4. w22.06 19 ¶19-20
Tuesday, April 9
Ó kọ lu ère náà ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ tó jẹ́ irin àti amọ̀.—Dán. 2:34.
Ìjọba alágbára tó ṣàpẹẹrẹ ‘òkè ẹsẹ̀ àti ìka ẹsẹ̀ tó jẹ́ irin àti amọ̀’ ló ń ṣàkóso ayé lọ́wọ́ báyìí. Ìjọba náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló para pọ̀ di ìjọba náà, wọ́n sì wá ń pè é ní ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa ère inú àlá Nebukadinésárì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí ìjọba yìí yàtọ̀ sí àwọn ìjọba tó ti ṣàkóso kọjá. Bó ṣe wà nínú ìran tí Dáníẹ́lì rí, ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ò dà bí àwọn ìjọba alágbára tó ti ṣàkóso ayé kọjá, àmọ́ Bíbélì sọ pé ìjọba náà máa jẹ́ irin àti amọ̀, kì í ṣe wúrà tàbí fàdákà. Amọ̀ náà ṣàpẹẹrẹ “ọmọ aráyé” tàbí àwọn mẹ̀kúnnù. (Dán. 2:43, àlàyé ìsàlẹ̀) Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí fi hàn pé àwọn mẹ̀kúnnù ń kó ipa tó lágbára lórí ọ̀rọ̀ ìbò, ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ìwọ́de àtàwọn àjọ òṣìṣẹ́. Ìyẹn kì í sì í jẹ́ kí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà lágbára láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. w22.07 4-5 ¶9-10
Wednesday, April 10
Oúnjẹ mi ni pé kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi.—Jòh. 4:34.
Kí ló ń dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi? Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni kó o bi ara ẹ pé, ‘Kí ló ń dá mi dúró?’ (Ìṣe 8:36) Kíyè sí i pé Jésù fi ṣíṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ wé oúnjẹ. Kí nìdí? Ìdí ni pé oúnjẹ máa ń ṣara wa lóore. Jésù mọ̀ pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ní ká ṣe máa ṣe wá láǹfààní. Jèhófà ò fẹ́ ká ṣe ohun tó máa pa wá lára. Ṣé ìrìbọmi wà lára ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni. (Ìṣe 2:38) Torí náà, mọ̀ dájú pé tó o bá tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run tó sọ pé kó o ṣèrìbọmi, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Tó bá ń wù ẹ́ láti tètè jẹ oúnjẹ kan tó o fẹ́ràn, kí ló wá ń dí ẹ lọ́wọ́ láti tètè ṣèrìbọmi? Kí ló ń dá ẹ dúró láti ṣèrìbọmi? Ọ̀pọ̀ èèyàn lè sọ pé “Mi ò tíì ṣe tán.” Òótọ́ kan ni pé ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù tó o lè ṣe ni pé kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó o sì ṣèrìbọmi. Torí náà, ó yẹ kó o ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà kó o tó ṣèpinnu, ìyẹn sì máa gbàkókò àti iṣẹ́ àṣekára. w23.03 7 ¶18-20
Thursday, April 11
Ó sọ pé, “àti fún ọmọ rẹ,” ìyẹn ẹnì kan ṣoṣo, tó jẹ́ Kristi.—Gál. 3:16.
Ìgbà tí Ọlọ́run fẹ̀mí yan Jésù ló di ẹni àkọ́kọ́ nínú ọmọ obìnrin náà. Lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì jíǹde, Ọlọ́run fi “ògo àti ọlá dé e ládé,” ó sì fún un ní “gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé.” Yàtọ̀ síyẹn, ó fún un lágbára láti “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (Héb. 2:7; Mát. 28:18; 1 Jòh. 3:8) Yàtọ̀ sí Jésù, àwọn míì wà lára ọmọ obìnrin náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ẹni tí wọ́n jẹ́ nígbà tó ń bá àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró sọ̀rọ̀, ó ní: “Bí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, ẹ jẹ́ ọmọ Ábúráhámù lóòótọ́, ajogún nípasẹ̀ ìlérí.” (Gál. 3:28, 29) Tí Jèhófà bá fẹ̀mí yan Kristẹni kan, ẹni náà ti di ara ọmọ obìnrin náà nìyẹn. Torí náà, Jésù Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó máa bá a ṣàkóso ni ọmọ obìnrin náà. (Ìfi. 14:1) Gbogbo wọn ló sì fìwà jọ Jèhófà Bàbá wọn. w22.07 16 ¶8-9
Friday, April 12
Mo kórìíra ayé mi gidigidi, mi ò fẹ́ wà láàyè mọ́.—Jóòbù 7:16.
Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá à ń gbé yìí, ohun tó dájú ni pé ìṣòro á máa bá wa fínra. (2 Tím. 3:1) Nírú àkókò yẹn, nǹkan lè tojú sú wa ká sì rẹ̀wẹ̀sì, pàápàá tó bá jẹ́ pé bí ìṣòro kan ṣe ń lọ ni òmíì ń tẹ̀ lé e tàbí táwọn ìṣòro náà dé sígbà kan náà. Ẹ rántí pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, ó sì máa jẹ́ ká lè fìgboyà kojú ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá wa. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ran ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Jóòbù lọ́wọ́. Oríṣiríṣi ìṣòro tó ń tánni lókun ló dé bá Jóòbù láàárín àkókò díẹ̀. Ní ọjọ́ kan péré, wọ́n mú ìròyìn burúkú wá fún Jóòbù pé gbogbo ẹran ọ̀sìn ẹ̀ ló ti kú, wọ́n tún sọ fún un pé àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀ ti kú. (Jóòbù 1:13-19) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù yìí ṣì ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a nígbà tí àìsàn kan tún kọ lù ú. Àìsàn náà ń ríni lára, ó sì ń jẹ́ kára ro ó gan-an. (Jóòbù 2:7) Jèhófà rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù. Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Jóòbù, ó ràn án lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò tó dé bá a kó lè jẹ́ olóòótọ́. w22.08 11 ¶8-10
Saturday, April 13
Àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí.—Héb. 12:6.
Tí wọ́n bá bá wa wí, ó máa ń dùn wá gan-an. A lè máa rò pé wọn ò dájọ́ náà bó ṣe tọ́ tàbí pé ìbáwí náà ti le jù. Tá a bá nírú èrò yìí, ìbáwí náà lè má ṣe wá láǹfààní tó yẹ, ó sì lè má jẹ́ ká rí i pé torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ló ṣe bá wa wí. (Héb. 12:5, 11) Torí náà, gba ìbáwí, kó o sì ṣàtúnṣe. Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí Jésù bá Pétérù wí níṣojú àwọn àpọ́sítélì tó kù. (Máàkù 8:33; Lúùkù 22:31-34) Ẹ ò rí i pé ìyẹn máa kó ìtìjú bá Pétérù gan-an! Síbẹ̀, Pétérù ṣì jẹ́ olóòótọ́ sí Jésù. Ó gba ìbáwí tí Jésù fún un, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe tó ṣe. Torí náà, Jèhófà bù kún Pétérù torí pé ó jẹ́ olóòótọ́, ó sì fún un ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. (Jòh. 21:15-17; Ìṣe 10:24-33; 1 Pét. 1:1) Tí wọ́n bá bá wa wí, tí ìbáwí náà sì kó ìtìjú bá wa, tá a bá gba ìbáwí náà tá a sì ṣàtúnṣe, ó máa ṣe àwa àtàwọn míì láǹfààní gan-an. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àtàwọn ará wa. w22.11 21-22 ¶6-7
Sunday, April 14
Kí o fi [Ísákì] rú ẹbọ sísun níbẹ̀.—Jẹ́n. 22:2.
Ábúráhámù mọ̀ pé Jèhófà ò ní hùwà ìkà láé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Ábúráhámù gbà pé Jèhófà lè jí Ísákì ọmọ òun dìde. (Héb. 11:17-19) Ó ṣe tán, Jèhófà ti ṣèlérí pé Ísákì máa di bàbá orílẹ̀-èdè, Ísákì ò sì tíì bí ọmọ kankan lásìkò yẹn. Torí pé Ábúráhámù nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó fọkàn tán Jèhófà pé ohun tó tọ́ ló máa ṣe. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Jèhófà ní kí Ábúráhámù ṣe ò rọrùn, ó nígbàgbọ́, ó sì ṣègbọràn. (Jẹ́n. 22:1-12) Báwo la ṣe lè fara wé Ábúráhámù? Bíi ti Ábúráhámù, ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àá sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Sm. 73:28) A máa dá ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn á sì jẹ́ ká máa ronú lọ́nà tí Jèhófà ń gbà ronú. (Héb. 5:14) Torí pé a ti dá ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́, tẹ́nì kan bá sọ pé ká ṣe ohun tí ò dáa, a ò ní gbà. Ìdí sì ni pé a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa dun Jèhófà, tó sì máa ba àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ jẹ́. w22.08 28-29 ¶11-12
Monday, April 15
Àníyàn inú ọkàn máa ń mú kó rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ ọ̀rọ̀ rere máa ń mú kó túra ká.—Òwe 12:25.
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pa dà sí Lísírà, Íkóníónì àti Áńtíókù, wọ́n “yan àwọn alàgbà fún wọn nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan.” (Ìṣe 14:21-23) Ó dájú pé àwọn alàgbà tí wọ́n yàn yẹn tu àwọn ará ìjọ nínú bí àwọn alàgbà ṣe ń ṣe láwọn ìjọ wa lóde òní. Ẹ̀yin alàgbà, ẹ máa kíyè sí àwọn ará tó níṣòro tẹ́ ẹ lè sọ “ọ̀rọ̀ rere” fún, kẹ́ ẹ sì tù wọ́n nínú. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà pé Jèhófà ló ran “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” lọ́wọ́ tí wọ́n fi fara da ìṣòro tí wọ́n dojú kọ. (Héb. 12:1) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ìtàn àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó fara da oríṣiríṣi ìṣòro nígbà àtijọ́ lè fún àwọn ará lókun kí wọ́n lè nígboyà, kí wọ́n sì máa ronú nípa “ìlú Ọlọ́run alààyè.” (Héb. 12:22) Àwọn ìtàn yẹn ti ran àwa náà lọ́wọ́ lónìí. Ẹ wo bí ìgbàgbọ́ wa ṣe túbọ̀ máa ń lágbára tá a bá ka ìtàn bí Jèhófà ṣe ran Gídíónì, Bárákì, Dáfídì, Sámúẹ́lì àtàwọn míì lọ́wọ́!—Héb. 11:32-35. w22.08 21-22 ¶5-6
Tuesday, April 16
A ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.—Ìfi. 20:13.
Báwo ni Jèhófà ṣe máa ṣèdájọ́ àwọn tó jíǹde bí “iṣẹ́ ọwọ́” wọn ṣe rí? Ṣé nǹkan tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó kú ló máa fi dá wọn lẹ́jọ́? Rárá o! Ẹ rántí pé Jèhófà ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n nígbà tí wọ́n kú. Torí náà, “iṣẹ́ ọwọ́ wọn” ò lè jẹ́ nǹkan tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó kú. Dípò bẹ́ẹ̀, nǹkan tí wọ́n bá ṣe lẹ́yìn tá a ti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nínú ayé tuntun ni Jèhófà máa fi dá wọn lẹ́jọ́. Kódà, àwọn ọkùnrin olóòótọ́ bíi Nóà, Sámúẹ́lì, Dáfídì àti Dáníẹ́lì máa ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù Kristi, kí wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà rẹ̀. Tó bá gba pé káwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, ṣé kò wá yẹ káwọn aláìṣòdodo kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀? Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kò mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wọn láti tún wà láàyè? Ìfihàn 20:15 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ní: ‘Ẹnikẹ́ni tí a kò rí i pé wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè la máa jù sínú adágún iná náà.’ Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn gan-an nìyẹn, Jèhófà máa pa wọ́n run títí láé. Ẹ ò rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí Jèhófà kọ orúkọ wa sínú ìwé ìyè, kó má sì pa á rẹ́ títí láé! w22.09 19 ¶17-19
Wednesday, April 17
Mo máa ń fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn mi mọ́ níwájú Ọlọ́run àti èèyàn.—Ìṣe 24:16.
Ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti fi Bíbélì kọ́ la fi ń pinnu bá a ṣe máa tọ́jú ara wa àti irú ìtọ́jú tá a máa gbà. (1 Tím. 3:9) Tá a bá ṣèpinnu kan, tá a sì fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ fáwọn ẹlòmíì, á dáa ká máa rántí ìlànà tó wà ní Fílípì 4:5 pé: “Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.” Tá a bá jẹ́ olóye, a ò ní máa ṣàníyàn jù nípa ìlera wa. Tí ìpinnu àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa bá sì yàtọ̀ sí tiwa, a ṣì máa ń nífẹ̀ẹ́ wọn, a sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn. (Róòmù 14:10-12) Jèhófà ni Orísun ìyè, a sì lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn tó fún wa yìí tá a bá ń tọ́jú ara wa dáadáa, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀. (Ìfi. 4:11) Ní báyìí, a ṣì ń ṣàìsàn, àjálù sì ń ṣẹlẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe nǹkan tí Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ kó máa ṣẹlẹ̀ sí wa nìyẹn. Láìpẹ́ ó máa fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, kò ní sí ìrora kankan mọ́, kò sì ní sí ikú mọ́. (Ìfi. 21:4) Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, ní báyìí tá a ṣì wà láàyè, ẹ jẹ́ ká máa tọ́jú ara wa ká lè máa fayọ̀ sin Jèhófà Bàbá wa ọ̀run nìṣó! w23.02 25 ¶17-18
Thursday, April 18
A ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mídíà àti Páṣíà.—Dán. 5:28.
Jèhófà ti fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé òun lágbára ju àwọn “aláṣẹ onípò gíga” lọ. (Róòmù 13:1) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mẹ́ta kan. Fáráò ọba Íjíbítì mú àwọn èèyàn Jèhófà lẹ́rú, ó sì kọ̀ láti tú wọn sílẹ̀. Àmọ́ Ọlọ́run dá wọn sílẹ̀, ó sì pa Fáráò sínú Òkun Pupa. (Ẹ́kís. 14:26-28; Sm. 136:15) Nígbà tí Bẹliṣásárì ọba Bábílónì se àsè ńlá kan, ‘ó gbé ara rẹ̀ ga sí Olúwa ọ̀run, ó sì ń yin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi fàdákà àti wúrà’ ṣe dípò Jèhófà. (Dán. 5:22, 23) Àmọ́ Ọlọ́run rẹ ọba agbéraga yìí wálẹ̀. “Òru ọjọ́ yẹn gan-an” ni wọ́n pa Bẹliṣásárì, Jèhófà sì gbé ìjọba ẹ̀ fún àwọn ará Mídíà àti Páṣíà. (Dán. 5:30, 31) Ọba Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kìíní ti ilẹ̀ Palẹ́sìnì pa àpọ́sítélì Jémíìsì. Ó tún fi àpọ́sítélì Pétérù sẹ́wọ̀n kí wọ́n lè pa á, àmọ́ Jèhófà ò jẹ́ kí Hẹ́rọ́dù rí i ṣe. Bíbélì sọ pé “áńgẹ́lì Jèhófà kọ lù ú,” ó sì kú.—Ìṣe 12:1-5, 21-23. w22.10 15 ¶12
Friday, April 19
Màá fetí sí yín.—Jer. 29:12.
Tá a bá ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ nígbà àtijọ́, ó máa jẹ́ kí ìrètí tá a ní túbọ̀ dá wa lójú. Gbogbo nǹkan tó wà nínú Bíbélì “ni a kọ fún wa láti gba ẹ̀kọ́, kí a lè ní ìrètí nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.” (Róòmù 15:4) Máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù àti Sérà. Wọ́n ti dàgbà kọjá ẹni tó lè bímọ, síbẹ̀ Jèhófà ṣèlérí fún wọn pé wọ́n máa rọ́mọ bí. (Jẹ́n. 18:10) Kí ni Ábúráhámù wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ó ní ìgbàgbọ́ pé òun máa di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 4:18) Lójú èèyàn, ó lè dà bíi pé kò ṣeé ṣe, àmọ́ ó dá Ábúráhámù lójú pé Jèhófà máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Jèhófà náà ò sì já a kulẹ̀. (Róòmù 4:19-21) Irú àwọn ìtàn Bíbélì bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. w22.10 27 ¶13-14
Saturday, April 20
O sì máa fi ojú ara rẹ rí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá.—Àìsá. 30:20.
Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ṣẹ nígbà tí wọ́n dá àwọn Júù sílẹ̀ nígbèkùn. Jèhófà fi hàn pé lóòótọ́ lòun jẹ́ Olùkọ́ wọn Atóbilọ́lá torí pé ó tọ́ wọn sọ́nà, ó sì jẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí láti mú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò. Bákan náà lónìí, inú tiwa náà ń dùn pé Jèhófà ni Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá. Lẹ́yìn tí Àìsáyà pe Jèhófà ní Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá, ó pè wá ní akẹ́kọ̀ọ́, ó sì sọ pé: O “máa fi ojú ara rẹ rí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá.” Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, Àìsáyà fi Jèhófà wé Olùkọ́ kan tó dúró níwájú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Torí náà, a mọyì àǹfààní tá a ní pé Jèhófà ń kọ́ wa lónìí. Báwo ni Jèhófà ṣe ń kọ́ wa? Ó ń kọ́ wa nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Inú wa dùn pé Jèhófà ń lo ètò rẹ̀ láti máa tọ́ wa sọ́nà. Àwọn ìtọ́sọ́nà tá à ń rí gbà nípàdé, èyí tá à ń kà nínú àwọn ìwé wa, tá à ń gbọ́ lórí ètò Tẹlifíṣọ̀n JW àtàwọn ọ̀nà míì máa ń jẹ́ ká fara dà á nígbà ìṣòro, ó sì ń mú ká láyọ̀. w22.11 10 ¶8-9
Sunday, April 21
Kí ló máa jẹ́ àmì . . . ìparí ètò àwọn nǹkan?—Mát. 24:3.
Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí Jerúsálẹ́mù máa pa run àti “ìparí ètò àwọn nǹkan” tá à ń gbé báyìí, ó ní: “Ní ti ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí yẹn, kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run àti Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àyàfi Baba.” Lẹ́yìn náà, ó kìlọ̀ fún gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n “wà lójúfò,” kí wọ́n sì “máa ṣọ́nà.” (Máàkù 13:32-37) Ó ṣe pàtàkì pé káwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ máa ṣọ́nà torí ìyẹn ló máa gba ẹ̀mí wọn là. Jésù ti jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí wọ́n á fi mọ ìgbà tí Jerúsálẹ́mù máa pa run. Ó sọ pé: “Tí ẹ bá rí i tí àwọn ọmọ ogun pàgọ́ yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tó máa dahoro ti sún mọ́lé.” Tó bá dìgbà yẹn, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù, kí wọ́n sì “bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.” (Lúùkù 21:20, 21) Àwọn tó ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù yìí ló là á já nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù run. Àkókò tí òpin ayé máa dé là ń gbé báyìí. Torí náà, àwa náà gbọ́dọ̀ máa ṣọ́nà, ká sì wà lójúfò. w23.02 14 ¶1-3
Monday, April 22
Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́.—Sm. 31:5.
Jèhófà ń kọ́ àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ pé ká jẹ́ olóòótọ́, ká sì máa ṣòdodo. Ìyẹn máa ń jẹ́ káwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún wa, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀. (Òwe 13:5, 6) Ṣé Jèhófà ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìwọ náà bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? O ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ohun tó dáa jù ni Jèhófà máa ń ṣe fáwa èèyàn, ohun tó sì ń ṣe fún ìwọ náà nìyẹn. (Sm. 77:13) Ìdí nìyẹn tó fi ń wù ẹ́ láti máa ṣòdodo. (Mát. 6:33) Ó yẹ kó o máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé irọ́ ni Sátánì pa mọ́ ọn. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Bó o ṣe ń gbé ìgbé ayé ẹ ló máa fi hàn bóyá o nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo, ìyẹn ló máa jẹ́ kó o lè sọ fún Sátánì pé: “Mi ò gba irọ́ ẹ gbọ́, òtítọ́ ni mo gbà gbọ́. Jèhófà ni mo fẹ́ kó jẹ́ Alákòóso mi, ohun tó bá sì sọ pé ó tọ́ ni màá ṣe.” Kí lá jẹ́ kó o ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀? Ohun tó máa jẹ́ kó o ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o gbàdúrà sí Jèhófà láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún un, kó o sì ṣèrìbọmi, kí gbogbo èèyàn lè mọ̀ pé o ti ya ara ẹ sí mímọ́. Tó bá jẹ́ lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo, wàá ṣèrìbọmi. w23.03 3 ¶4-5
Tuesday, April 23
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín, kí ìbẹ̀rù má sì mú kí ọkàn yín dà rú.—Jòh. 14:27.
Àlàáfíà kan wà tí ọ̀pọ̀ nínú ayé lónìí ò mọ̀. Ìyẹn ni “àlàáfíà Ọlọ́run” tó máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ torí pé a ní àjọse tó dáa pẹ̀lú Bàbá wa ọ̀run. Tá a bá ní àlàáfíà Ọlọ́run, ọkàn wa máa balẹ̀. (Fílí. 4:6, 7) Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń jẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. A sì tún máa ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú “Ọlọ́run àlàáfíà” fúnra rẹ̀. (1 Tẹs. 5:23) Torí náà, tá a bá mọ Bàbá wa ọ̀run, tá a gbẹ́kẹ̀ lé e, tá a sì ń ṣègbọràn sí i, àlàáfíà Ọlọ́run máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ tí ìṣòro bá dé bá wa. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe ká ní àlàáfíà Ọlọ́run, kí ọkàn wa sì balẹ̀ tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀ ládùúgbò wa, tí wọ́n bá ń jagun abẹ́lé tàbí tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí wa? Tí ọ̀kan lára àwọn nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù máa ń bà wá gan-an. Inú wa dùn pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Bí wọ́n ṣe ń fara da onírúurú ìṣòro ni Jèhófà ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ìyẹn sì ń mú kí ọkàn wọn balẹ̀. w22.12 16 ¶1-2
Wednesday, April 24
Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín. Ẹ máa ṣẹrú fún Jèhófà.—Róòmù 12:11.
A ò lè pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa. Torí náà, kò yẹ ká fi iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe díwọ̀n bá a ṣe wúlò fún Jèhófà tó tàbí ká máa fi wé iṣẹ́ ìsìn táwọn ẹlòmíì ń ṣe. (Gál. 6:4) Torí náà, ó yẹ ká wo àwọn ọ̀nà míì tá a lè gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ká sì máa sin Jèhófà nìṣó. Tó o bá jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn, tó ò sì tọrùn bọ gbèsè, á rọrùn fún ẹ láti gba àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ètò Ọlọ́run. Ní àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ ẹ lè tètè tẹ̀, ìyẹn sì máa jẹ́ kó o mọ bí ọwọ́ ẹ ṣe máa tẹ àwọn àfojúsùn tó máa gba àkókò díẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó bá wù ẹ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, o lè kọ́kọ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún àwọn oṣù kan. Tó bá wù ẹ́ láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, máa lo àkókò tó pọ̀ sí i lóde ẹ̀rí. Àwọn nǹkan tó ò ń ṣe yìí máa jẹ́ kó o lè gba iṣẹ́ ìsìn tó pọ̀ sí i lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, pinnu pé wàá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún ẹ. w22.04 26 ¶16-17
Thursday, April 25
Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nítorí ó ń gbọ́ ohùn mi, ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.—Sm. 116:1.
Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wa, ó sì tún ń jẹ́ ká máa láyọ̀ bá a ṣe ń sìn ín. Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó yọ wá nínú ìṣòro kan tó ń bá wa fínra, ó lè jẹ́ ohun tó máa kọ́kọ́ ṣe ni pé kó fún wa lókun ká lè fara dà á. Tí Jèhófà ò bá mú ìṣòro náà kúrò nígbà tá a rò pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè gba pé ká máa gbàdúrà sí i léraléra pé kó fún wa lókun ká lè máa fara dà á nìṣó. Ohun tó sì rọ̀ wá pé ká ṣe nìyẹn. Ọ̀rọ̀ tí Àìsáyà sọ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Má ṣe jẹ́ [kí Jèhófà] sinmi rárá.” (Àìsá. 62:7) Kí ni gbólóhùn yìí túmọ̀ sí? Ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Jèhófà lemọ́lemọ́ débi tó fi máa dà bíi pé a ò jẹ́ kó sinmi. Ọ̀rọ̀ tí Àìsáyà sọ yìí jẹ́ ká rántí àwọn àpèjúwe tí Jésù sọ nípa àdúrà ní Lúùkù 11:8-10, 13. Jésù rọ̀ wá níbẹ̀ pé tá a bá ń gbàdúrà, ká “máa béèrè” pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́. w22.11 8 ¶1; 9 ¶6-7
Friday, April 26
A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ Ìjọba Ọlọ́run.—Ìṣe 14:22.
Ìwọ àti ìdílé ẹ lè múra sílẹ̀ de inúnibíni báyìí. Dípò kó o máa ronú nípa gbogbo ohun tí ò dáa tó lè ṣẹlẹ̀ nígbà inúnibíni, ṣe ni kó o máa ṣe ohun táá jẹ́ kí àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára, kó o sì ran àwọn ọmọ ẹ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tẹ́rù bá ń bà ẹ́, sọ gbogbo bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà. (Sm. 62:7, 8) Kí ìwọ àti ìdílé ẹ jíròrò ìdí tó fi yẹ kẹ́ ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Tí ìwọ àtàwọn ọmọ ẹ bá jọ múra sílẹ̀ de inúnibíni bẹ́ ẹ ṣe múra sílẹ̀ de àjálù, ó máa jẹ́ káwọn náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n nígboyà, kọ́kàn wọn sì balẹ̀. Àlàáfíà Ọlọ́run máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. (Fílí. 4:6, 7) Bá a tiẹ̀ ń ṣàìsàn, tí àjálù ń ṣẹlẹ̀ sí wa, tí wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wa, Jèhófà máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ torí pé Ọlọ́run àlàáfíà ni. Ó máa ń lo àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó wa. Ó sì fẹ́ kí gbogbo wa máa ran ara wa lọ́wọ́. Ní báyìí táwa èèyàn Jèhófà ṣì ń gbádùn àlàáfíà, a máa lè múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro ńlá tó ń bọ̀, títí kan “ìpọ́njú ńlá.”—Mát. 24:21. w22.12 27 ¶17-18
Saturday, April 27
Kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.—Mát. 9:13.
Kò yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tá a ti dá sẹ́yìn. Àmọ́ ṣá, a ò gbọ́dọ̀ fi ẹbọ ìràpadà Jésù kẹ́wọ́ ká wá “mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà.” (Héb. 10:26-31) Ó dájú pé tá a bá ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a wá ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà pèsè nípasẹ̀ àwọn alàgbà, tá a sì yí ìwà wa pa dà, Jèhófà ti dárí jì wá pátápátá nìyẹn. (Àìsá. 55:7; Ìṣe 3:19) Ẹbọ ìràpadà Jésù lágbára láti nu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, ó sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti gbé inú Párádísè títí láé. Yàtọ̀ síyẹn, ìgbésí ayé nínú Párádísè ò ní sú wa rárá. Ìgbà gbogbo làá máa bá àwọn èèyàn tó níwà rere pàdé, àá sì máa ṣe iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ojoojúmọ́ làá máa mọ Bàbá wa ọ̀run sí i, tí àá sì máa gbádùn ohun tó ń pèsè fún wa. Àwọn ohun tá a máa kọ́ nípa Jèhófà ò ní lópin, a sì máa rí ohun púpọ̀ kọ́ lára àwọn nǹkan tó dá. w22.12 13 ¶17, 19
Sunday, April 28
Màá mú kí ìwọ àti obìnrin náà di ọ̀tá.—Jẹ́n. 3:15.
“Obìnrin náà” kò lè jẹ́ Éfà. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé ọmọ obìnrin náà máa “fọ́” orí ejò náà. Sátánì ni ejò yẹn, kò sì sí èèyàn aláìpé tó jẹ́ ọmọ Éfà tó lè fọ́ orí Èṣù. Ta lẹni tó máa wá pa Èṣù run? Ìwé Ìfihàn jẹ́ ká mọ obìnrin tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ nípa ẹ̀. (Ìfi. 12:1, 2, 5, 10) Obìnrin yìí kì í ṣe èèyàn! Òṣùpá wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá (12) sì wà ní orí rẹ̀. Ó bí ọmọ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an, Ìjọba Ọlọ́run sì ni ọmọ náà. Ọ̀run ni Ìjọba náà wà, torí náà ọ̀run ni obìnrin náà gbọ́dọ̀ wà. Obìnrin náà ṣàpẹẹrẹ apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́. (Gál. 4:26) Bíbélì jẹ́ ká mọ ẹni àkọ́kọ́ nínú ọmọ obìnrin náà. Ó sọ pé ọmọ náà máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù.—Jẹ́n. 22:15-18. w22.07 15-16 ¶6-8
Monday, April 29
Ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ èèyàn, àmọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ lóòótọ́, bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—1 Tẹs. 2:13.
Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n pọ̀ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìmọ̀ràn inú Bíbélì máa ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní, ó sì máa ń yí ìgbésí ayé wọn pa dà. Nígbà tí Mósè kọ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ inú Bíbélì, ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run pé: “Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí kò wúlò fún yín, àmọ́ òun ló máa mú kí ẹ wà láàyè.” (Diu. 32:47) Ìgbésí ayé àwọn tó ń ṣe ohun tí Bíbélì sọ máa ń dáa, wọ́n sì máa ń láyọ̀. (Sm. 1:2, 3) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ti wà tipẹ́, àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣì wúlò, ó sì ń mú kí ìgbésí ayé àwọn èèyàn dáa sí i. Kò sígbà táwọn ìlànà inú ẹ̀ kì í ṣe wá láǹfààní, gbogbo èèyàn tó ń gbé ayé ló sì ń ṣe láǹfààní. Bá a ṣe ń ka Ìwé Mímọ́ yìí, tá a sì ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà, Ọlọ́run tó ni Bíbélì máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè fi ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé wa. (Sm. 119:27; Mál. 3:16; Héb. 4:12) Torí náà, Ọlọ́run tó ni Bíbélì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́! w23.02 3 ¶5-6
Tuesday, April 30
Ó máa mú ìparun wá lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.—Dán. 8:24.
Ìfihàn orí 13 sọ fún wa pé orí keje ẹranko náà, ìyẹn Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso ayé ń ṣe bí ẹranko ẹhànnà tó ní “ìwo méjì bí ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ bíi dírágónì.” Ẹranko yìí “ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó lágbára, kódà ó ń mú kí iná wá láti ọ̀run sí ayé lójú aráyé.” (Ìfi. 13:11-15) Ìfihàn orí 16 àti 19 pe ẹranko ẹhànnà yìí ní “wòlíì èké.” (Ìfi. 16:13; 19:20) Dáníẹ́lì náà sọ ohun tó jọ ọ́, ó ní Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso ayé “máa runlérùnnà.” (Dán. 8:19, 23, 24, àlàyé ìsàlẹ̀) Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló ṣe bọ́ǹbù átọ́míìkì méjì tí wọ́n yìn láti fòpin sí ogun náà. Torí náà, a lè sọ pé Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso ayé “mú kí iná wá láti ọ̀run sí ayé.” w22.05 10 ¶9