ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es24 ojú ìwé 47-57
  • May

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • May
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Wednesday, May 1
  • Thursday, May 2
  • Friday, May 3
  • Saturday, May 4
  • Sunday, May 5
  • Monday, May 6
  • Tuesday, May 7
  • Wednesday, May 8
  • Thursday, May 9
  • Friday, May 10
  • Saturday, May 11
  • Sunday, May 12
  • Monday, May 13
  • Tuesday, May 14
  • Wednesday, May 15
  • Thursday, May 16
  • Friday, May 17
  • Saturday, May 18
  • Sunday, May 19
  • Monday, May 20
  • Tuesday, May 21
  • Wednesday, May 22
  • Thursday, May 23
  • Friday, May 24
  • Saturday, May 25
  • Sunday, May 26
  • Monday, May 27
  • Tuesday, May 28
  • Wednesday, May 29
  • Thursday, May 30
  • Friday, May 31
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
es24 ojú ìwé 47-57

May

Wednesday, May 1

Lẹ́yìn èyí . . . mo rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn, tí èèyàn kankan kò lè ka iye wọn, wọ́n wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n.—Ìfi. 7:9.

Lẹ́yìn tí Jòhánù rí àwọn tó wà lọ́run, ó tún rí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn.” Wọn ò dà bí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) torí pé Bíbélì ò sọ iye wọn. Kí ni Bíbélì sọ nípa wọn? Áńgẹ́lì kan sọ fún Jòhánù pé: “Àwọn yìí ni àwọn tó wá látinú ìpọ́njú ńlá náà, wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìfi. 7:14) Tí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” náà bá ti la ìpọ́njú ńlá já, wọ́n á máa gbé ayé, wọ́n á sì máa gbádùn ọ̀pọ̀ ohun rere tí Ọlọ́run pèsè. (Sm. 37:​9-11, 27-29; Òwe 2:​21, 22; Ìfi. 7:​16, 17) Bóyá Ọlọ́run yàn wá pé ká lọ sí ọ̀run tàbí ká máa gbé ayé, ṣé a gbà pé a máa wà níbẹ̀ nígbà táwọn nǹkan tó wà nínú ìwé Ìfihàn orí 7 yẹn bá ṣẹ? Ó yẹ ká wà níbẹ̀. Ẹ ò rí i pé àkókò aláyọ̀ nìgbà yẹn máa jẹ́ fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó máa gbé ọ̀run àtàwọn tó máa gbé ayé! Inú wa máa dùn gan-an pé a ti àkóso Jèhófà lẹ́yìn. w22.05 16 ¶6-7

Thursday, May 2

Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fúnni ní ọgbọ́n.—Òwe 2:6.

Ó dájú pé tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì, o máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ lọ́gbọ́n, ohun tó sì yẹ kó o ṣe nìyẹn. (Jém. 1:5) Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Ọgbọ́n ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ.” (Òwe 4:7) Ó dájú pé kì í ṣe ọgbọ́n kan lásán ni Sólómọ́nì ń sọ, ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ló ń sọ. Àmọ́ ṣé ọgbọ́n Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tá à ń ní lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ohun tó máa jẹ́ ká di ọlọ́gbọ́n ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́, ká sì máa fi ìmọ̀ràn tí àwọn èèyàn méjì kan fún wa sílò torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọgbọ́n wọn ti wá. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Sólómọ́nì. Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye tó pọ̀ gan-an.” (1 Ọba 4:29) Lẹ́yìn náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Jésù tó gbọ́n jù lọ láyé. (Mát. 12:42) Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù pé: “Ẹ̀mí Jèhófà máa bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye.”—Àìsá. 11:2. w22.05 20 ¶1-2

Friday, May 3

Jẹ́ kí n lè sọ nípa agbára rẹ fún ìran tó ń bọ̀.—Sm. 71:18.

Kò sẹ́ni tó dàgbà jù láti ní àwọn ohun kan lọ́kàn tó fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Beverley tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75). Àìsàn tó ń ṣe é máa ń jẹ́ kó nira fún un láti rìn. Àmọ́, ó wù ú pé kóun náà pe àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Torí náà, ó fi ṣe àfojúsùn ẹ̀. Nígbà tí ọwọ́ Beverley tẹ àfojúsùn náà, inú ẹ̀ dùn gan-an. Nígbà táwọn míì rí ohun tó ṣe, àwọn náà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Jèhófà mọyì gbogbo nǹkan táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ti dàgbà ń ṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́ mọ́. (Sm. 71:17) Àwọn nǹkan tó o mọ̀ pé ọwọ́ ẹ lè tẹ̀ ni kó o fi ṣe àfojúsùn ẹ. Máa hùwà tó máa jẹ́ kínú Jèhófà dùn sí ẹ. Kọ́ iṣẹ́ tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ wúlò fún Ọlọ́run àti ètò rẹ̀. Túbọ̀ máa yọ̀ǹda ara ẹ láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ lọ́wọ́. Torí náà bíi ti Tímótì, Jèhófà máa bù kún ẹ, “gbogbo èèyàn [sì máa] rí i kedere pé ò ń tẹ̀ síwájú.”—1 Tím. 4:15. w22.04 27 ¶18-19

Saturday, May 4

Láti kékeré jòjòló lo ti mọ ìwé mímọ́.—2 Tím. 3:15.

Ká sọ pé ládúrú gbogbo ohun tẹ́ ẹ ti ṣe, ọ̀kan lára àwọn ọmọ yín sọ pé òun ò fẹ́ sin Jèhófà ńkọ́? Má rò pé o ti di aláṣetì. Ìdí sì ni pé gbogbo wa ni Jèhófà ti fún láǹfààní láti yan ohun tá a fẹ́, ìyẹn ni pé ká pinnu bóyá a máa jọ́sìn òun tàbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Má sọ̀rètí nù, ó ṣì lè pa dà lọ́jọ́ kan. Rántí àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá. (Lúùkù 15:​11-19, 22-24) Ọ̀dọ́kùnrin yẹn ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tí ò dáa, àmọ́ nígbà tó yá, ó pa dà wálé. Ẹ̀yin òbí, Jèhófà ti fún yín láǹfààní ńlá kan. Àǹfààní náà ni pé ẹ̀yin lẹ máa tọ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà lákòókò wa yìí. (Sm. 78:​4-6) Iṣẹ́ kékeré kọ́ nìyẹn o, a sì gbóríyìn fún yín bẹ́ ẹ ṣe ń ṣiṣẹ́ láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tẹ́ ẹ sì ń tọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìmọ̀ràn rẹ̀. Ó dájú pé inú Bàbá wa ọ̀run máa dùn sí yín gan-an.—Éfé. 6:4. w22.05 30-31 ¶16-18

Sunday, May 5

Gbogbo ara ti para pọ̀ di ọ̀kan.—Éfé. 4:16.

Kí àlàáfíà tó lè wà nínú ìjọ, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni nígbà àtijọ́. Ohun tí wọ́n lè ṣe yàtọ̀ síra, ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì ní. (1 Kọ́r. 12:​4, 7-11) Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí wọ́n máa bá ara wọn díje tàbí kó fa ìyapa láàárín wọn. Dípò bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe “láti gbé ara Kristi ró.” Ó kọ̀wé sáwọn ará Éfésù pé: “Tí ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, èyí á mú kí ara máa dàgbà sí i bó ṣe ń gbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.” (Éfé. 4:​1-3, 11, 12) Nígbà tí wọ́n fi ìmọ̀ràn yìí sílò, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ. Ohun táwa náà sì ń ṣe lónìí nìyẹn. Pinnu pé o ò ní máa fi ara ẹ wé àwọn ẹlòmíì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù, kó o sì sapá láti fìwà jọ ọ́. Má gbàgbé pé Jèhófà “kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́” rẹ. (Héb. 6:10) Ó mọyì gbogbo ohun tóò ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. w22.04 14 ¶15-16

Monday, May 6

Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là.—1 Tím. 1:15.

Inú wa dùn pé àwa kọ́ ni Jèhófà ní ká máa pinnu bóyá kóun dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tàbí kóun má dárí jì í! Àmọ́ nígbà míì, nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ pé àwa la máa pinnu ohun tá a máa ṣe. Kí ni nǹkan náà? Ẹnì kan lè ṣẹ̀ wá, kódà nǹkan tó ṣe lè dùn wá gan-an, àmọ́ kó wá bẹ̀ wá pé ká dárí ji òun. Nígbà míì sì rèé, ẹni náà lè má bẹ̀ wá rárá. Síbẹ̀, kò yẹ ká di onítọ̀hún sínú, ṣe ló yẹ ká dárí jì í bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà lè dùn wá gan-an, kó sì múnú bí wa. Lóòótọ́, ó lè má rọrùn fún wa láti tètè dárí jì í, pàápàá tó bá jẹ́ pé ohun tó ṣe ò dáa rárá. Ilé Ìṣọ́ September 15, 1994 sọ pé: “Tí o bá dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan, ìyẹn ò sọ pé o fojú kéré ẹ̀ṣẹ̀ náà. Àwa Kristẹni gbà pé tá a bá ti dárí ji ẹnì kan tọkàntọkàn, a ti fi ọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́ nìyẹn. Òun ni Onídàájọ́ òdodo gbogbo ayé, ó sì máa mú ìdájọ́ òdodo ṣẹ ní àkókò tó tọ́.” w22.06 9 ¶6-7

Tuesday, May 7

Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.—Sm. 27:14.

Jèhófà ṣèlérí pé òun máa kó àwọn èèyàn jọ látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n, òun á sì jẹ́ kí wọ́n jọ máa ṣe ìjọsìn mímọ́. Lónìí, àwùjọ àwọn èèyàn yìí la wá mọ̀ sí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn.” (Ìfi. 7:​9, 10) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà tí wọ́n wá látinú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà nínú àwùjọ yìí, wọ́n jẹ́ ẹni àlàáfíà, wọ́n sì wà níṣọ̀kan kárí ayé. (Sm. 133:1; Jòh. 10:16) Gbogbo ìgbà ni wọ́n ṣe tán láti sọ̀rọ̀ nípa ayé tuntun fún àwọn tó bá fẹ́ gbọ́. (Mát. 28:​19, 20; Ìfi. 14:​6, 7; 22:17) Tó o bá wà lára àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn yìí, ó dájú pé o máa mọyì àwọn ohun rere tí Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé lọ́jọ́ iwájú. Èṣù fẹ́ ká máa rò pé a ò nírètí kankan. Ohun tó fẹ́ ká máa rò ni pé Jèhófà ò ní mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Tá a bá jẹ́ kí Sátánì mú ká sọ̀rètí nù, a ò ní nígboyà mọ́, kódà a lè má sin Jèhófà mọ́. w22.06 20-21 ¶2-3

Wednesday, May 8

A ní ìrètí yìí bí ìdákọ̀ró fún ọkàn, ó dájú, ó fìdí múlẹ̀.—Héb. 6:19.

Ìrètí tá a ní máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ torí a mọ̀ pé nǹkan ṣì máa dáa. Ẹ rántí pé Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sí wa. (Jòh. 15:20) Torí náà, tá a bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà sọ pé òun máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú, á rọrùn fún wa láti máa jọ́sìn ẹ̀ nìṣó. Ẹ jẹ́ ká wo bí ìrètí tí Jésù ní ṣe jẹ́ kó dúró gbọin-in bó tiẹ̀ mọ̀ pé ikú oró lòun máa kú. Lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì 33 S.K., àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ kan tó wà nínú ìwé Sáàmù tó jẹ́ ká mọ bí ọkàn Jésù ṣe balẹ̀ tó, ó ní: “Màá sì máa fi ìrètí gbé ayé; torí o ò ní fi mí sílẹ̀ nínú Isà Òkú, bẹ́ẹ̀ ni o ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́. . . . Wàá mú kí ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi níwájú rẹ.” (Ìṣe 2:​25-28; Sm. 16:​8-11) Jésù nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa jí òun dìde àti pé òun máa láǹfààní láti tún pa dà wà pẹ̀lú Bàbá òun lọ́run.—Héb. 12:​2, 3. w22.10 25 ¶4-5

Thursday, May 9

Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.—Jém. 3:2.

Ìgbà kan wà tí méjì lára àwọn àpọ́sítélì Jésù, ìyẹn Jémíìsì àti Jòhánù ní kí ìyá wọn sọ fún Jésù pé kó fi àwọn sípò ńlá nínú Ìjọba rẹ̀. (Mát. 20:​20, 21) Ohun tí Jémíìsì àti Jòhánù ṣe yìí fi hàn pé wọ́n ní ìgbéraga, wọ́n sì ń fẹ́ ipò ọlá. (Òwe 16:18) Kì í ṣe Jémíìsì àti Jòhánù nìkan ló ṣe ohun tí ò dáa lásìkò yẹn. Wo ohun táwọn àpọ́sítélì yòókù ṣe. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí àwọn mẹ́wàá yòókù gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bínú sí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò náà.” (Mát. 20:24) Ẹ fojú inú wo bí Jémíìsì àti Jòhánù á ṣe máa bá àwọn àpọ́sítélì yòókù jiyàn lórí ọ̀rọ̀ náà. Kí ni Jésù ṣe nígbà tó rí àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ tí wọ́n ń jiyàn? Jésù ò gbaná jẹ. Kò sọ pé òun máa yan àwọn àpọ́sítélì míì tó dáa jù wọ́n lọ, tí wọ́n nírẹ̀lẹ̀ gan-an, tí wọ́n á sì máa fìfẹ́ hàn síra wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù fi sùúrù tọ́ wọn sọ́nà torí ó mọ̀ pé wọn kì í ṣèèyàn burúkú. (Mát. 20:​25-28) Jésù ṣì ń fìfẹ́ hàn sí wọn láìka àìpé wọn sí. w23.03 28-29 ¶10-13

Friday, May 10

Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn mi yọ̀,kí n lè fún ẹni tó ń pẹ̀gàn mi lésì.—Òwe 27:11.

Ọ̀pọ̀ nǹkan lo ti ṣe kó o tó ṣèrìbọmi. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọdún mélòó kan lo fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa. Àwọn nǹkan tó o kọ́ ti jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, o ti wá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó ni Bíbélì. Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà wá lágbára gan-an débi tó o fi ya ayé ẹ sí mímọ́ fún un tó o sì ṣèrìbọmi. Ìyẹn mà dáa gan-an o! Bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú, ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti dán ìgbàgbọ́ ẹ wò kó o tó ṣèrìbọmi. Àmọ́ bí àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà ṣe ń lágbára sí i, àwọn àdánwò míì á máa yọjú. Sátánì á máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà má bàa lágbára mọ́, kó o má sì sìn ín mọ́. (Éfé. 4:14) O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Kí ló máa jẹ́ kó o jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kó o sì mú ìlérí ẹ ṣẹ pé òun ni wàá máa sìn? Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o máa “tẹ̀ síwájú” kó o lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀.—Héb. 6:1. w22.08 2 ¶1-2

Saturday, May 11

Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ, bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe pa á láṣẹ fún ọ gẹ́lẹ́, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn, kí nǹkan sì lè máa lọ dáadáa fún ọ.—Diu. 5:16.

Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé ló yẹ kó máa pa ọ̀rọ̀ àṣírí ìdílé wọn mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìyàwó arákùnrin kan lè ní ìwà kan tó máa ń pa ọkọ ẹ̀ lẹ́rìn-ín. Àmọ́, ṣé ó yẹ kó sọ ọ̀rọ̀ náà fáwọn èèyàn, kó sì wá kó ìtìjú bá ìyàwó ẹ̀? Kò yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀! Ó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀, kò sì ní fẹ́ ṣe ohun tó máa bà á nínú jẹ́. (Éfé. 5:33) Àwọn ọ̀dọ́ máa ń fẹ́ ká bọ̀wọ̀ fáwọn náà. Ó yẹ káwọn òbí fi kókó yìí sọ́kàn, torí ọ̀wọ̀ díẹ̀díẹ̀ lara ń fẹ́. Kò yẹ káwọn òbí máa sọ àṣìṣe ọmọ wọn fáwọn èèyàn torí ìyẹn máa kó ìtìjú bá àwọn ọmọ náà. (Kól. 3:21) Ó yẹ káwọn ọmọ náà gbọ́n, kò sì yẹ kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ àṣírí ìdílé wọn fáwọn èèyàn torí ìyẹn lè kó ìtìjú bá àwọn ará ilé wọn. Torí náà, tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé bá ń ṣe ipa tiẹ̀ láti pa ọ̀rọ̀ àṣírí mọ́, ìdílé wọn á túbọ̀ wà níṣọ̀kan. w22.09 10 ¶9

Sunday, May 12

Fetí sí èyí, Jóòbù. Dúró, kí o sì fara balẹ̀ ronú.—Jóòbù 37:14.

Jèhófà rán Jóòbù létí bí ọgbọ́n òun ṣe pọ̀ tó àti bóun ṣe ń fìfẹ́ bójú tó àwọn nǹkan tóun dá. Ó tún sọ fún un nípa bí agbára àwọn ẹranko tóun dá ṣe pọ̀ tó àti oríṣiríṣi nǹkan táwọn ẹranko náà máa ń ṣe. (Jóòbù 38:​1, 2; 39:​9, 13, 19, 27; 40:15; 41:​1, 2) Jèhófà tún lo ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Élíhù láti tu Jóòbù nínú kó sì fún un lókun. Élíhù fi dá Jóòbù lójú pé Jèhófà máa ń san àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́san tí wọ́n bá fara da àdánwò. Àmọ́ Jèhófà tún mú kí Élíhù fìfẹ́ bá Jóòbù wí. Élíhù jẹ́ kí Jóòbù rí i pé kò yẹ kó máa ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé kò já mọ́ nǹkan kan tó bá fi ara ẹ̀ wé Jèhófà tó dá ayé àtọ̀run. Jèhófà tún gbé iṣẹ́ kan fún Jóòbù pé kó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Jóòbù 42:​8-10) Báwo ni Jèhófà ṣe ń ran àwa náà lọ́wọ́ lónìí tá a bá dojú kọ àdánwò tó le gan-an? Jèhófà kì í bá wa sọ̀rọ̀ bó ṣe bá Jóòbù sọ̀rọ̀, àmọ́ ó máa ń fi Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá wa sọ̀rọ̀.—Róòmù 15:4. w22.08 11 ¶10-11

Monday, May 13

Ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn má jẹ ẹran tàbí kó má mu ọtí tàbí kó má ṣe ohunkóhun tó máa mú arákùnrin rẹ̀ kọsẹ̀.—Róòmù 14:21.

Àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni àtàwọn Kèfèrí tó di Kristẹni ló wà ní ìjọ Róòmù. Nígbà tí Òfin Mósè kásẹ̀ nílẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ò tẹ̀ lé òfin tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn oúnjẹ kan mọ́. (Máàkù 7:19) Àtìgbà yẹn làwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù ti lómìnira láti jẹ oúnjẹ tó bá wù wọ́n. Àmọ́ àwọn Júù kan tó jẹ́ Kristẹni sọ pé àwọn ò lè jẹ oúnjẹ tí Òfin sọ pé káwọn má jẹ. Ọ̀rọ̀ yìí dá ìyapa sáàárín àwọn ará inú ìjọ nígbà yẹn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín wọn. Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà rí ìpalára tí irú àríyànjiyàn bẹ́ẹ̀ lè ṣe fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn àti gbogbo ìjọ lápapọ̀. (Róòmù 14:​19, 20) Bákan náà, ó gbà láti má ṣe àwọn nǹkan tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́, kó má bàa mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀. (1 Kọ́r. 9:​19-22) Táwa náà ò bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ dá ìyapa sáàárín wa, àá máa gbé ara wa ró, àlàáfíà á sì wà láàárín wa. w22.08 22 ¶7

Tuesday, May 14

Jèhófà . . . nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń wá òdodo.—Òwe 15:9.

Tá a bá ní ohun kan lọ́kàn tá a fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àá máa sapá kọ́wọ́ wa lè tẹ̀ ẹ́. Ohun kan náà la máa ṣe tá a bá ń wá òdodo. Jèhófà á máa fi sùúrù ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa tẹ̀ síwájú, àá sì máa sunwọ̀n sí i bá a ṣe ń wá òdodo. (Sm. 84:​5, 7) Nítorí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa, ó jẹ́ ká mọ̀ pé kò nira fún wa láti máa ṣòdodo. (1 Jòh. 5:3) Torí náà, tá a bá ń ṣòdodo, ó máa dáàbò bò wá lójoojúmọ́. Ṣé ẹ rántí ìhámọ́ra ogun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀? (Éfé. 6:​14-18) Èwo nínú àwọn ìhámọ́ra yẹn ló máa ń dáàbò bo ọkàn àwọn ọmọ ogun? “Àwo ìgbàyà òdodo” tó ṣàpẹẹrẹ àwọn ìlànà òdodo Jèhófà ni. Bí àwo ìgbàyà ṣe máa ń dáàbò bo ọkàn ọmọ ogun kan, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìlànà òdodo Jèhófà máa ń dáàbò bo èrò inú wa, ìyẹn ẹni tá a jẹ́ gan-an. Torí náà, rí i pé àwo ìgbàyà òdodo wà lára ìhámọ́ra ogun rẹ!—Òwe 4:23. w22.08 29 ¶13-14

Wednesday, May 15

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa máa wà títí láé.—Àìsá. 40:8.

Ọjọ́ pẹ́ tí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń tọ́ àwọn olóòótọ́ ọkùnrin àti obìnrin sọ́nà. Kí ló jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe? Jèhófà jẹ́ káwọn èèyàn ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn èèyàn yẹn, wọ́n fara balẹ̀ dà á kọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀mọ̀wé kan ń sọ̀rọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó sọ pé: “A lè fi gbogbo ẹnu sọ pé kò sí ìwé àtijọ́ kankan tí wọ́n da ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ kọ lọ́nà tó péye bíi Bíbélì.” Torí náà, ó dá wa lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run là ń kà nínú Bíbélì lónìí torí pé Jèhófà ló ni ín. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé” ti wá. (Jém. 1:17) Ọ̀kan lára ẹ̀bùn tó dáa jù lọ tí Jèhófà fún wa ni Bíbélì. Tẹ́nì kan bá fún wa lẹ́bùn, ẹ̀bùn náà fi hàn pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì tún mọ ohun tá a fẹ́. Bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tó fún wa ní Bíbélì ṣe rí náà nìyẹn. Tá a bá ń ka Bíbélì déédéé, àá túbọ̀ mọ̀ ọ́n. Á jẹ́ ká rí i pé Jèhófà mọ̀ wá dáadáa, ó sì mọ ohun tá a fẹ́. w23.02 2-3 ¶3-4

Thursday, May 16

Ó dájú pé ìmọ̀ Jèhófà máa bo ayé.—Àìsá. 11:9.

Ẹ ò rí i pé ọjọ́ àgbàyanu lọjọ́ yẹn máa jẹ́ nígbà tí Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ sí í jí àwọn èèyàn dìde nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi! Gbogbo àwọn téèyàn wọn ti kú lara wọn á ti wà lọ́nà láti rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú. Bó ṣe rí lára Jèhófà náà nìyẹn. (Jóòbù 14:15) Ẹ wo bínú àwọn èèyàn ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú. “Àwọn olódodo” tórúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè máa ní “àjíǹde ìyè.” (Ìṣe 24:15; Jòh. 5:29) Ó sì ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn wa wà lára àwọn tó máa kọ́kọ́ jí dìde sí ayé lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì. Yàtọ̀ síyẹn, “àwọn aláìṣòdodo” ìyẹn àwọn tí kò láǹfààní láti mọ Jèhófà tàbí láti jọ́sìn ẹ̀ kí wọ́n tó kú máa ní “àjíǹde ìdájọ́.” Gbogbo àwọn tó bá jí dìde la máa dá lẹ́kọ̀ọ́. (Àìsá. 26:9; 61:11) Torí náà, a máa bẹ̀rẹ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá ò ṣerú ẹ̀ rí nínú ìtàn aráyé.—Àìsá. 11:10. w22.09 20 ¶1-2

Friday, May 17

Òun ni Ọlọ́run alààyè.—Dán. 6:26.

Jèhófà fi hàn pé òun lágbára ju àgbájọ àwọn ọba orílẹ̀-èdè lọ. Jèhófà jà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọba Kénáánì mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31), wọ́n sì gba èyí tó pọ̀ jù lára Ilẹ̀ Ìlérí. (Jóṣ. 11:​4-6, 20; 12:​1, 7, 24) Léraléra ni Jèhófà ti fi hàn pé òun ni Ẹni Tó Lágbára Jù Lọ! Ìgbà kan wà tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì fọ́nnu nípa ‘agbára àti okun àti ògo ọlá ńlá’ tó ní dípò kó gbà pé Jèhófà ni Ẹni tí ìyìn yẹ, torí náà, Jèhófà mú kó ya wèrè. Lẹ́yìn tí ara Nebukadinésárì yá, ó “yin Ẹni Gíga Jù Lọ,” ó sì wá gbà pé “àkóso tó wà títí láé ni àkóso [Jèhófà].” Ó tún sọ pé: “Kò sí ẹni tó lè dá a dúró.” (Dán. 4:​30, 33-35) Onísáàmù kan sọ pé: “Aláyọ̀ ni orílẹ̀-èdè tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, àwọn èèyàn tí ó ti yàn láti jẹ́ ohun ìní rẹ̀.” (Sm. 33:12) Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nítorí àwọn nǹkan rere tó ń ṣe fún wa yìí! w22.10 15-16 ¶13-15

Saturday, May 18

Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.—Sm. 119:160.

Ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ nínú Bíbélì ti jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ohun tí Jèhófà sọ pé òun máa ṣe lọ́jọ́ iwájú máa ṣẹ. Ó ń ṣe wá bíi ti onísáàmù tó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.” (Sm. 119:81) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ti fún wa ní “ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.” (Jer. 29:11) Jèhófà ló máa ṣe àwọn nǹkan tá à ń retí lọ́jọ́ iwájú, kì í ṣe àwọn èèyàn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì, ìyẹn lá jẹ́ ká túbọ̀ máa gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nǹkan míì tó jẹ́ ká gbára lé Bíbélì ni pé ó máa ń yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà tí wọ́n bá ń fi ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sílò. (Sm. 119:​66, 138) Bí àpẹẹrẹ, àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n fẹ́ kọ ara wọn sílẹ̀ ti ń fayọ̀ gbé pa pọ̀ báyìí. Inú àwọn ọmọ wọn ń dùn torí àwọn òbí wọn ń fìfẹ́ bójú tó wọn, wọ́n sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Éfé. 5:​22-29. w23.01 5 ¶12-13

Sunday, May 19

Ẹ jẹ́ kí ìrètí tí ẹ ní máa fún yín láyọ̀.—Róòmù 12:12.

Ronú nípa àǹfààní tó o ti rí nígbà tó o kà nípa àwọn ìlérí Jèhófà tó wà nínú Bíbélì tó ti ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, Jésù ṣèlérí pé Bàbá òun máa pèsè àwọn nǹkan tó o nílò fún ẹ. (Mát. 6:​32, 33) Ó tún fi dá ẹ lójú pé tó o bá béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, á fún ẹ. (Lúùkù 11:13) Ó sì dájú pé Jèhófà ti ṣe àwọn nǹkan yìí fún ẹ. Ó ṣeé ṣe kó o rántí àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún ẹ tó sì mú ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣèlérí pé òun máa dárí jì ẹ́, òun máa tù ẹ́ nínú, òun á sì máa fi ọ̀rọ̀ òun bọ́ ẹ. (Mát. 6:14; 24:45; 2 Kọ́r. 1:3) Torí náà, tó o bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti ṣe fún ẹ, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé ó máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Onísáàmù kan sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni . . . tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, . . . Ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ nígbà gbogbo.”—Sm. 146:​5, 6. w22.10 27 ¶15; 28 ¶17

Monday, May 20

Jèhófà máa tàn sára rẹ.—Àìsá. 60:2.

Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe pa dà bọ̀ sípò kàn wá lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni! Lọ́nà wo? Látọdún 1919 S.K., ọ̀pọ̀ èèyàn ti bọ́ nínú ìgbèkùn Bábílónì ńlá, ìyẹn àpapọ̀ gbogbo ẹ̀sìn èké ayé. Wọ́n sì ti wà níbi tó dáa ju Ilẹ̀ Ìlérí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Inú Párádísè tẹ̀mí ni wọ́n wà báyìí. (Àìsá. 51:3; 66:8) Àtọdún 1919 S.K. làwọn ẹni àmì òróró ti ń gbádùn Párádísè tẹ̀mí. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn tó nírètí láti gbé ayé, ìyẹn “àwọn àgùntàn mìíràn” náà ti wá sínú Párádísè tẹ̀mí yìí, àwọn náà sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Jòh. 10:16; Àìsá. 25:6; 65:13) Párádísè tẹ̀mí wà kárí ayé. Ibi yòówù ká máa gbé, àwa náà lè wà nínú Párádísè tẹ̀mí yìí tá a bá ti pinnu pé ìjọsìn mímọ́ làá máa ṣe. w22.11 11-12 ¶12-15

Tuesday, May 21

Jèhófà, ṣebí láti ayérayé ni ìwọ ti wà? Ọlọ́run mi, Ẹni Mímọ́ mi, ìwọ kì í kú.—Háb. 1:12.

Ṣé ó ṣòro fún ẹ láti gbà pé Jèhófà ti wà láti ayérayé, tó sì máa wà “títí ayé”? (Àìsá. 40:28) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣòro fún láti gbà bẹ́ẹ̀. Élíhù náà sọ nípa Ọlọ́run pé: “Iye àwọn ọdún rẹ̀ kọjá òye wa.” (Jóòbù 36:26) Àmọ́ torí pé nǹkan kan ò yé wa ò túmọ̀ sí pé nǹkan yẹn ò sí. Bí àpẹẹrẹ, a lè má mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí iná mànàmáná ṣe ń ṣiṣẹ́, àmọ́ ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò síná mànàmáná? Rárá! Lọ́nà kan náà, àwa èèyàn ò lè mọ ìdí tó fi jẹ́ pé láti ayérayé ni Jèhófà ti wà àti pé kò lè kú láé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò yé wa délẹ̀délẹ̀, ìyẹn ò sọ pé Jèhófà ò ní wà láàyè títí láé. Agbára Jèhófà ò mọ síbi tí òye wa dé. (Róòmù 11:​33-36) Kódà, kí àwọn nǹkan tó wà lágbàáyé yìí tó wà ni Jèhófà ti wà. Bí àpẹẹrẹ, kí oòrùn tó wà ni Jèhófà ti wà. Yàtọ̀ síyẹn, ó ti wà kó tó “na ọ̀run bí aṣọ.”—Jer. 51:15. w22.12 2-3 ¶3-4

Wednesday, May 22

Kí àdúrà mi dà bíi tùràrí tí a ṣètò sílẹ̀ níwájú rẹ.—Sm. 141:2.

Nígbà míì, wọ́n lè fún wa láǹfààní pé ká gbàdúrà. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó fẹ́ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè sọ pé kí arábìnrin tí wọ́n jọ lọ gbàdúrà. Arábìnrin tí wọ́n ní kó gbàdúrà náà lè má mọ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà dáadáa, torí náà, ó lè sọ pé á dáa kóun gbàdúrà ìparí. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, á ti mọ akẹ́kọ̀ọ́ yẹn dé àyè kan kí wọ́n tó parí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ìyẹn á sì jẹ́ kó mọ ohun tó máa sọ nínú àdúrà ẹ̀ táá ṣe akẹ́kọ̀ọ́ náà láǹfààní. Wọ́n lè sọ pé kí arákùnrin kan gbàdúrà nípàdé iṣẹ́ ìwàásù tàbí nípàdé ìjọ. Kò yẹ káwọn arákùnrin tó láǹfààní yẹn gbàgbé ìdí tá a fi wà nípàdé. Kò yẹ kí wọ́n fi àdúrà yẹn ṣe ìfilọ̀ fáwọn ará tàbí kí wọ́n fi nà wọ́n lẹ́gba ọ̀rọ̀. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìpàdé wa ló jẹ́ pé ìṣẹ́jú márùn-ún péré ni ètò Ọlọ́run ní ká fi kọrin, ká sì fi gbàdúrà. Torí náà, kò yẹ kí arákùnrin tó máa gbàdúrà sọ “ọ̀rọ̀ púpọ̀,” pàápàá níbẹ̀rẹ̀ ìpàdé.—Mát. 6:7. w22.07 24 ¶17-18

Thursday, May 23

Ẹ máa gbọ́ nípa àwọn ogun, ẹ sì máa gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ogun. Kí ẹ rí i pé ẹ ò bẹ̀rù, torí àwọn nǹkan yìí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, àmọ́ òpin ò tíì dé.—Mát. 24:6.

Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àjàkálẹ̀ àrùn máa wà “láti ibì kan dé ibòmíì.” (Lúùkù 21:11) Báwo lohun tí Jésù sọ yìí ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀? Kì í yà wá lẹ́nu tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀. A mọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ló ń ṣẹ. Torí náà, ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Jésù fún àwa tá à ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ó sọ pé: “Ẹ rí i pé ẹ ò bẹ̀rù.” Ó dájú pé tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀, àwọn ohun kan wà tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀ tó ò ní lè ṣe mọ́. Àmọ́, má jẹ́ kíyẹn dí ẹ lọ́wọ́ láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí lọ sípàdé. Àwọn ìtàn ìgbésí ayé tó wà nínú àwọn ìwé àtàwọn fídíò wa máa ń rán wa létí pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà tí wọ́n nírú ìṣòro bẹ́ẹ̀. w22.12 17 ¶4, 6

Friday, May 24

Ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo èèyàn.—Oníw. 9:​11, àlàyé ìsàlẹ̀.

Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀ Jósẹ́fù gan-an, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. (Jẹ́n. 37:​3, 4) Torí náà, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú ẹ̀. Nígbà tí àǹfààní ẹ̀ yọ, wọ́n ta Jósẹ́fù fáwọn oníṣòwò ilẹ̀ Mídíánì. Àwọn oníṣòwò yẹn mú Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì tó jìnnà gan-an sí ìlú ẹ̀, àmọ́ àwọn náà tún tà á fún Pọ́tífárì tó jẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ Fáráò. Ẹ wo bí ìgbésí ayé Jósẹ́fù ṣe yí pa dà lójijì, ọmọ tó jẹ́ ààyò bàbá ẹ̀ wá di ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì! (Jẹ́n. 39:1) Nígbà míì, ìṣòro tó dé bá wa lè jẹ́ èyí tó “máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn,” ìyẹn ìṣòro tó ń bá gbogbo èèyàn fínra. (1 Kọ́r. 10:13) Ohun míì ni pé ìyà lè jẹ wá torí pé a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, kí wọ́n ta kò wá tàbí kí wọ́n ṣe inúnibíni sí wa torí ohun tá a gbà gbọ́. (2 Tím. 3:12) Àmọ́ ìṣòro yòówù kó dé bá ẹ, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. w23.01 14-15 ¶3-4

Saturday, May 25

Níbi tí kò bá sí igi, iná á kú.—Òwe 26:20.

Nígbà míì, ó yẹ ká lọ bá ẹni tá a jọ ń sin Jèhófà tó ṣẹ̀ wá, ká lè yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ ká tó ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká kọ́kọ́ bi ara wa láwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣé mo mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó mú kó hùwà yẹn sí mi?’ (Òwe 18:13) ‘Ṣé ó lè jẹ́ pé kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó ṣe?’ (Oníw. 7:20) ‘Ṣé èmi náà ti hu irú ìwà yẹn rí?’ (Oníw. 7:​21, 22) ‘Tí mo bá lọ bá ẹni yẹn, ṣéyẹn máa yanjú ọ̀rọ̀ náà àbí ṣe ló máa dá kún un?’ Tá a bá ronú lórí àwọn ìbéèrè yẹn dáadáa, a lè wá rí i pé ìfẹ́ tá a ní fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa máa mú ká gbójú fo ọ̀rọ̀ náà. A máa fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ ni wá, tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láìwo ibi tí wọ́n kù sí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ ẹ̀sìn tòótọ́, kí wọ́n sì wá dara pọ̀ mọ́ wa láti máa jọ́sìn Jèhófà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa fìfẹ́ hàn síra wa torí òun la fi ń dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ mọ̀. w23.03 31 ¶18-19

Sunday, May 26

Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.—1 Jòh. 4:8.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ ni ànímọ́ tó ta yọ jù lọ tí Ọlọ́run ní. Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, kò jẹ́ kí wọ́n kọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tá ò nílò sínú Bíbélì. (Jòh. 21:25) Jèhófà tún fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa torí ó fi Bíbélì bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó buyì kún wa. Nínú Bíbélì, Jèhófà ò fún wa lófin jàǹrànjanran nípa ohun tó yẹ ká ṣe àtohun tí ò yẹ ká ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí wọ́n kọ ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ń múnú wa dùn àtàwọn ìmọ̀ràn tó wúlò sínú Bíbélì, ká lè fi ṣe ìpinnu tó tọ́. Àwọn nǹkan tí wọ́n kọ sínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí ló jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká sì máa ṣègbọràn sí i látọkàn wá. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tí ìtàn wọn wà nínú Bíbélì yé wa dáadáa, torí èèyàn tó “mọ nǹkan lára bíi tiwa” ni wọ́n. (Jém. 5:17) Àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn èèyàn bíi tiwa lọ́wọ́, á túbọ̀ dá wa lójú pé “Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó sì jẹ́ aláàánú.”—Jém. 5:11. w23.02 6 ¶13-15

Monday, May 27

Ẹ máa ronú bó ṣe tọ́, ẹ wà lójúfò!—1 Pét. 5:8.

Àwọn ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ìwé tó kẹ́yìn Bíbélì sọ pé: “Ìfihàn látọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fún un, kó lè fi àwọn nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn ẹrú rẹ̀.” (Ìfi. 1:1) Torí náà, ó máa ń wù wá láti mọ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti báwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa wọn ṣe ń ṣẹ, ká sì tún máa sọ̀rọ̀ nípa wọn láàárín ara wa. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì láàárín ara wa, kò yẹ ká máa méfò nípa àwọn nǹkan tá a rò pé ó máa ṣẹlẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé a ò ní fẹ́ sọ ohunkóhun tó máa da ìṣọ̀kan ìjọ rú. Bí àpẹẹrẹ, a lè gbọ́ báwọn alákòóso ayé ṣe ń sọ báwọn ṣe máa yanjú àwọn rògbòdìyàn kan tó ń ṣẹlẹ̀, káwọn sì jẹ́ kí àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ wà. Dípò ká máa sọ pé ohun táwọn alákòóso ayé sọ ti jẹ́ ká rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ inú 1 Tẹsalóníkà 5:3 ti ṣẹ, ṣe ló yẹ ká lọ wo ohun tí ètò Ọlọ́run sọ kẹ́yìn nípa ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé nǹkan tí ètò Ọlọ́run ń kọ́ wa là ń bá àwọn ará sọ, gbogbo ìjọ ló máa ní “èrò kan náà.”—1 Kọ́r. 1:10; 4:6. w23.02 16 ¶4-5

Tuesday, May 28

Máa gẹṣin lọ nítorí òtítọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo, ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì ṣe àwọn ohun àgbàyanu.—Sm. 45:4.

Kí nìdí tó o fi nífẹ̀ẹ́ Jésù Kristi? Ìdí ni pé Jésù nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo, ó sì nírẹ̀lẹ̀. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo, ìyẹn fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jésù Kristi náà. Ronú nípa bí Jésù Kristi ṣe fìgboyà sọ òtítọ́, tó sì ṣe ohun tó tọ́. (Jòh. 18:37) Àmọ́ báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ó fẹ́ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tí Jésù bá ṣe àṣeyọrí kan, Bàbá ẹ̀ ló máa ń yìn lógo, kì í yin ara ẹ̀. (Máàkù 10:​17, 18; Jòh. 5:19) Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o rí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ní? Ṣé kò mú kó o nífẹ̀ẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, kó o sì máa fara wé e? Ó dájú pé ó mú kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀ tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì ń fara wé e. (Sm. 18:35; Héb. 1:3) Ṣéyẹn ò jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jésù tó fìwà jọ Bàbá ẹ̀ pátápátá? w23.03 3-4 ¶6-7

Wednesday, May 29

Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.—Ìṣe 24:15.

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwùjọ méjì tí Jèhófà máa jí dìde, tí wọ́n sì máa láǹfààní láti gbé ayé títí láé. Bíbélì pè wọ́n ní “àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo.” “Àwọn olódodo” ni àwọn tó sin Jèhófà tọkàntọkàn kí wọ́n tó kú. Àmọ́ “àwọn aláìṣòdodo” ò sin Jèhófà kí wọ́n tó kú. Torí pé àwùjọ méjèèjì yìí máa jíǹde, ṣé a wá lè sọ pé orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè? Orúkọ “àwọn olódodo” ti wà nínú ìwé ìyè kí wọ́n tó kú. Àmọ́ ṣé Jèhófà wá yọ orúkọ wọn kúrò nínú ìwé ìyè nígbà tí wọ́n kú ni? Rárá o! Torí lójú Jèhófà, gbogbo wọn ló ṣì “wà láàyè.” Bíbélì sọ pé Jèhófà “kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, àmọ́ ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn alààyè, torí lójú rẹ̀, gbogbo wọn wà láàyè.” (Lúùkù 20:38) Ìyẹn ni pé nígbà tí Jèhófà bá jí àwọn olódodo dìde sí ayé, orúkọ wọn máa wà nínú ìwé ìyè bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ṣì lè pa orúkọ wọn rẹ́.—Lúùkù 14:14. w22.09 16 ¶9-10

Thursday, May 30

Jèhófà Ọlọ́run mú ọkùnrin náà, ó sì fi sínú ọgbà Édẹ́nì kó lè máa ro ó, kó sì máa tọ́jú rẹ̀.—Jẹ́n. 2:15.

Jèhófà fẹ́ kí ẹni tó kọ́kọ́ dá sáyé gbádùn àwọn nǹkan tóun dá. Nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù, ó fi í sínú Párádísè kan, ó sì ní kó máa bójú tó o kí gbogbo ayé lè di Párádísè. (Jẹ́n. 2:​8, 9) Ẹ wo bí inú Ádámù ṣe máa dùn tó nígbà tó rí bí àwọn igi eléso ṣe ń dàgbà táwọn ewéko sì ń yọ òdòdó. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni Ádámù ní pé Jèhófà gbéṣẹ́ fún un pé kó máa bójú tó ọgbà Édẹ́nì! Jèhófà tún sọ fún Ádámù pé kó sọ oríṣiríṣi ẹranko lórúkọ. (Jẹ́n. 2:​19, 20) Jèhófà fúnra ẹ̀ lè sọ àwọn ẹranko yẹn lórúkọ, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ádámù ló gbé iṣẹ́ yẹn fún. Kò sí àní-àní pé Ádámù máa kíyè sí àwọn ẹranko yẹn dáadáa. Á wo bí wọ́n ṣe rí àti bí wọ́n ṣe ń ṣe, kó tó sọ wọ́n lórúkọ. Ó dájú pé Ádámù máa gbádùn iṣẹ́ yẹn gan-an. Ó sì dájú pé iṣẹ́ yìí máa jẹ́ kó rí i pé ọlọ́gbọ́n ni Bàbá rẹ̀ ọ̀run torí pé àwọn nǹkan tó dá rẹwà gan-an, wọ́n sì máa jẹ́ ká gbádùn ayé wa. w23.03 15 ¶3

Friday, May 31

Ó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú, ó máa fòpin sí gbogbo wọn, òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.—Dán. 2:44.

Bó ṣe jẹ́ pé ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló ṣàpẹẹrẹ òkè ẹsẹ̀ àti ìka ẹsẹ̀ ère ńlá yẹn, òun ni Bíbélì sọ pé ó máa jẹ́ ìjọba alágbára tó máa ṣàkóso ayé kẹ́yìn. (Dán. 2:​31-33) Kò ní sí ìjọba èèyàn kankan tó máa dìde lẹ́yìn ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Ìjọba Ọlọ́run máa pa á run pẹ̀lú gbogbo ìjọba èèyàn tó kù. (Ìfi. 16:​13, 14, 16; 19:​19, 20) Àǹfààní wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣe wá? Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì jẹ́ ká rí ẹ̀rí míì tó fi hàn pé àkókò òpin là ń gbé. Ó ju ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ ọdún lọ (2,500) tí Dáníẹ́lì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìjọba alágbára mẹ́rin míì máa dìde lẹ́yìn Bábílónì, wọ́n sì máa pọ́n àwọn èèyàn Ọlọ́run lójú. Dáníẹ́lì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló máa ṣàkóso ayé kẹ́yìn lára àwọn ìjọba alágbára mẹ́rin náà. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó sì jẹ́ ká máa retí pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba èèyàn run, á sì máa ṣàkóso aráyé. w22.07 4 ¶9; 5 ¶11-12

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́