ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es24 ojú ìwé 57-67
  • June

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • June
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Saturday, June 1
  • Sunday, June 2
  • Monday, June 3
  • Tuesday, June 4
  • Wednesday, June 5
  • Thursday, June 6
  • Friday, June 7
  • Saturday, June 8
  • Sunday, June 9
  • Monday, June 10
  • Tuesday, June 11
  • Wednesday, June 12
  • Thursday, June 13
  • Friday, June 14
  • Saturday, June 15
  • Sunday, June 16
  • Monday, June 17
  • Tuesday, June 18
  • Wednesday, June 19
  • Thursday, June 20
  • Friday, June 21
  • Saturday, June 22
  • Sunday, June 23
  • Monday, June 24
  • Tuesday, June 25
  • Wednesday, June 26
  • Thursday, June 27
  • Friday, June 28
  • Saturday, June 29
  • Sunday, June 30
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
es24 ojú ìwé 57-67

June

Saturday, June 1

Ìdin àti iyẹ̀pẹ̀ tó ṣù pọ̀ bo ara mi; gbogbo awọ ara mi ti sé èépá, ó sì ń ṣọyún.—Jóòbù 7:5.

Jóòbù ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ó bímọ tó pọ̀, ìdílé ẹ̀ wà níṣọ̀kan, ó sì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. (Jóòbù 1:​1-5) Àmọ́ ní ọjọ́ kan ṣoṣo, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ohun tó ní ló pàdánù. Ohun àkọ́kọ́ tó pàdánù ni ọrọ̀ ẹ̀. (Jóòbù 1:​13-17) Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀ kú. Ẹ wo ìbànújẹ́ àti ọgbẹ́ ọkàn tó máa bá Jóòbù àti ìyàwó ẹ̀ àti bó ṣe máa jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ pé kì í ṣe ọmọ wọn kan péré ló kú, àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ni. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé Jóòbù fa aṣọ ẹ̀ ya, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì dákú lọ! (Jóòbù 1:​18-20) Lẹ́yìn ìyẹn, Sátánì mú kí àìsàn tó ń dójú tini kọ lu Jóòbù. (Jóòbù 2:​6-8) Kó tó dìgbà yẹn, àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún Jóòbù gan-an. Kódà, àwọn èèyàn máa ń wá gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ ẹ̀. (Jóòbù 31:18) Àmọ́ ní báyìí, àwọn èèyàn ti ń yẹra fún un. Wọ́n ta á nù, àwọn arákùnrin ẹ̀ pa á tì, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ fi í sílẹ̀, kódà àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ ò sún mọ́ ọn!—Jóòbù 19:​13, 14, 16. w22.06 21 ¶5-6

Sunday, June 2

Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú ká dàgbà sókè nínú ohun gbogbo.—Éfé. 4:15.

Lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi, ó yẹ kí gbogbo wa máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù. Ó gba àwọn Kristẹni yẹn níyànjú pé kí wọ́n “di géńdé.” (Éfé. 4:13) Lédè míì, ohun tó ń sọ ni pé, ‘Kí wọ́n máa tẹ̀ síwájú.’ O ti ṣe ohun tó fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Àmọ́, o ṣì lè jẹ́ kí ìfẹ́ náà máa lágbára sí i. Báwo lo ṣe máa ṣe é? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe é nínú Fílípì 1:9. Pọ́ọ̀lù gbàdúrà pé kí ìfẹ́ táwọn ará Fílípì ní fún Jèhófà “túbọ̀ pọ̀ gidigidi.” Torí náà, a lè jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà máa pọ̀ sí i. Ọ̀nà tá a lè gbà ṣe é ni pé ká ní “ìmọ̀ tó péye àti òye tó kún rẹ́rẹ́.” Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, tí àá sì mọyì àwọn ànímọ́ tó ní àti ọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan. Ó yẹ kó túbọ̀ máa wù wá láti ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn, ká má sì ṣe ohun tó máa bà á nínú jẹ́. Ó tún yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́, ká sì máa ṣe é. w22.08 2-3 ¶3-4

Monday, June 3

Ìfihàn látọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fún un, kó lè fi àwọn nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn ẹrú rẹ̀.—Ìfi. 1:1.

Kì í ṣe gbogbo èèyàn ni ìwé Ìfihàn wà fún, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tá a ti ya ara wa sí mímọ́ ló wà fún. Torí pé èèyàn Ọlọ́run ni wá, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé a wà lára àwọn tí àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí ń ṣẹ sí lára. Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ ìgbà tí àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ, ó sọ pé: “Mo wà ní ọjọ́ Olúwa nípasẹ̀ ìmísí.” (Ìfi. 1:10) Nígbà tí Jòhánù kọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ní nǹkan bí ọdún 96 S.K., ìgbà tí “ọjọ́ Olúwa” máa bẹ̀rẹ̀ ṣì jìnnà gan-an. (Mát. 25:​14, 19; Lúùkù 19:12) Àmọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914 nígbà tí Jésù di Ọba ní ọ̀run. Láti ọdún yẹn wá ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìfihàn tó dá lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, a ti wà ní “ọjọ́ Olúwa” báyìí!—Ìfi. 1:3. w22.05 2 ¶2-3

Tuesday, June 4

A sì mú ẹranko ẹhànnà náà pẹ̀lú wòlíì èké.—Ìfi. 19:20.

A ju ẹranko ẹhànnà náà pẹ̀lú wòlíì èké yẹn láàyè sínú adágún iná tó ń jó, tí a fi imí ọjọ́ sí. Torí náà, nígbà táwọn ìjọba tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run yìí ṣì ń ṣàkóso lọ́wọ́, Ọlọ́run máa pa wọ́n run ráúráú. Kí ló yẹ ká ṣe? Àwa Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀. (Jòh. 18:36) A ò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú ayé yìí. Àmọ́ ìyẹn kì í rọrùn rárá torí pé àwọn ìjọba máa ń fẹ́ ká ti àwọn lẹ́yìn ní gbogbo ọ̀nà. Àwọn tó bá ṣe ohun tí wọ́n sọ máa gba àmì ẹranko ẹhànnà náà. (Ìfi. 13:​16, 17) Àmọ́ inú Jèhófà ò ní dùn sí ẹnikẹ́ni tó bá gba àmì náà, kò sì ní jogún ìyè àìnípẹ̀kun. (Ìfi. 14:​9, 10; 20:4) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì ká má dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú rárá tí ìjọba bá tiẹ̀ ń fúngun mọ́ wa lójú méjèèjì! w22.05 10-11 ¶12-13

Wednesday, June 5

Ǹjẹ́ o ti rí ọkùnrin tó já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀? Yóò dúró níwájú àwọn ọba; kò ní dúró níwájú àwọn èèyàn yẹpẹrẹ.—Òwe 22:29.

Ohun tó o lè fi ṣe àfojúsùn ẹ ni pé kó o kọ́ iṣẹ́ tó o lè lò nínú ètò Ọlọ́run. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí á jẹ́ kó o lè ṣe púpọ̀ sí i. O lè ronú nípa iye àwọn òṣìṣẹ́ tá a fẹ́ kó yọ̀ǹda ara wọn láti bá wa kọ́ àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì wa, àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa. Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ yìí ló di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ torí pé wọ́n bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó mọṣẹ́ gan-an ṣiṣẹ́. Lónìí, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yẹn ń fojú síṣẹ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe máa tún àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ṣe. Ọ̀nà yìí àtàwọn ọ̀nà míì ni Jèhófà “Ọba ayérayé” àti Jésù Kristi “Ọba àwọn ọba” ń gbà gbé àwọn ohun ńlá ṣe nípasẹ̀ àwọn tó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́. (1 Tím. 1:17; 6:15) A fẹ́ ṣiṣẹ́ kára, ká sì lo àwọn ohun tá a mọ̀ ọ́n ṣe láti fi yin Jèhófà lógo, kì í ṣe láti fi gbé ara wa lárugẹ.—Jòh. 8:54. w22.04 24 ¶7; 25 ¶11

Thursday, June 6

Owó . . . jẹ́ ààbò.—Oníw. 7:12.

Sólómọ́nì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó sì gbádùn ara ẹ̀ dọ́ba. (1 Ọba 10:​7, 14, 15) Àmọ́ ní ti Jésù, ohun ìní díẹ̀ ló ní, kò sì nílé tara ẹ̀. (Mát. 8:20) Síbẹ̀, ojú tó tọ́ làwọn méjèèjì fi wo ohun ìní torí pé Jèhófà Ọlọ́run ló fún wọn lọ́gbọ́n. Sólómọ́nì gbà pé tá a bá lówó, àá lè ra àwọn ohun kòṣeémáàní àtàwọn nǹkan míì tá a nílò. Síbẹ̀, bí Sólómọ́nì ṣe lówó tó, ó gbà pé àwọn nǹkan kan wà tó ṣe pàtàkì ju owó lọ. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Orúkọ rere ló yẹ kéèyàn yàn dípò ọ̀pọ̀ ọrọ̀.” (Òwe 22:1) Sólómọ́nì tún sọ pé inú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó kì í fi bẹ́ẹ̀ dùn torí ohun tí wọ́n ní kì í tó wọn. (Oníw. 5:​10, 12) Ó sì kìlọ̀ fún wa pé ká má gbẹ́kẹ̀ lé owó torí pé owó tá a ní lè lọ lójijì.—Òwe 23:​4, 5. w22.05 21 ¶4-5

Friday, June 7

Jèhófà ń fi sùúrù dúró láti ṣojúure sí yín, ó sì máa dìde láti ṣàánú yín. Torí pé Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà. Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó ń retí rẹ̀.—Àìsá. 30:18.

Tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa, á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú, á dá wa lójú pé òun ló yẹ ká máa sìn títí láé. Àwọn nǹkan yìí lá jẹ́ ká máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó báyìí. Jèhófà “máa dìde” nítorí wa nígbà tó bá fẹ́ pa ayé búburú yìí run. Ó dá wa lójú pé “Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo” ni Jèhófà, kò sì ní jẹ́ kí ọjọ́ tó dá pé òun máa pa ayé búburú Sátánì yìí run kọjá láì ṣe nǹkan kan. (Àìsá. 25:9) Torí náà, à ń fi sùúrù dúró de ọjọ́ tí Jèhófà máa gbà wá là. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa mọyì àǹfààní tá a ní láti gbàdúrà, àá máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àá máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò, àá sì máa ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á, ká sì máa fayọ̀ sìn ín nìṣó. w22.11 13 ¶18-19

Saturday, June 8

Má pa ẹ̀kọ́ ìyá rẹ tì.—Òwe 1:8.

Lóòótọ́ Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìgbà tí Tímótì ṣèrìbọmi, àmọ́ ó dájú pé inú Yùníìsì ìyá ẹ̀ máa dùn gan-an lọ́jọ́ yẹn. (Òwe 23:25) Yùníìsì ṣàṣeyọrí láti kọ́ Tímótì kó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù Kristi. Ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn òbí Tímótì ń ṣe. Gíríìkì ni bàbá ẹ̀, àmọ́ Júù ni ìyá ẹ̀ àti ìyá ẹ̀ àgbà. (Ìṣe 16:1) Ó ṣeé ṣe kí Tímótì ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ nígbà tí Yùníìsì àti Lọ́ìsì di Kristẹni. Àmọ́ bàbá rẹ̀ kì í ṣe Kristẹni. Ẹ̀sìn wo ni Tímótì máa wá ṣe báyìí? Àwọn ìyá tó jẹ́ Kristẹni lónìí náà nífẹ̀ẹ́ ìdílé wọn gan-an. Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wọn ni bí wọ́n ṣe máa ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Jèhófà sì mọyì iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe. (Òwe 1:​8, 9) Jèhófà ti ran ọ̀pọ̀ ìyá lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè sìn ín. w22.04 16 ¶1-3

Sunday, June 9

Ọlọ́run ti fi sí ọkàn wọn láti ṣe ohun tí òun fẹ́.—Ìfi. 17:17.

Láìpẹ́, Jèhófà máa fi sọ́kàn àwọn ìjọba ayé “láti ṣe ohun tí òun fẹ́.” Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀? Àwọn ìjọba yẹn, ìyẹn “ọba mẹ́wàá” máa gbéjà ko àwọn ìsìn èké, wọ́n á sì pa wọ́n run. (Ìfi. 17:​1, 2, 12, 16) Báwo la ṣe mọ̀ pé Bábílónì Ńlá ò ní pẹ́ pa run? Ká tó dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ rántí pé alagbalúgbú omi Odò Yúfírétì ló yí Bábílónì ká, ó sì wà lára ohun tó ń dáàbò bò ó. Lọ́nà kan náà, ìwé Ìfihàn fi àìmọye èèyàn tó ń ti Bábílónì Ńlá lẹ́yìn wé “àwọn omi” tó ń dáàbò bò ó. (Ìfi. 17:15) Àmọ́, ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé omi náà máa “gbẹ,” tó fi hàn pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń ti àpapọ̀ gbogbo ìsìn èké ayé lẹ́yìn máa fi í sílẹ̀. (Ìfi. 16:12) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣẹ lónìí torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń fi ìsìn èké sílẹ̀, wọ́n sì ti wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ìṣòro wọn lọ sí ibòmíì. w22.07 5-6 ¶14-15

Monday, June 10

Ẹni tí kì í ṣàánú kò ní rí àánú gbà nígbà ìdájọ́. Àánú máa ń borí ìdájọ́.—Jém. 2:13.

Tá a bá ń dárí ji àwọn èèyàn, ìyẹn máa fi hàn pé a mọyì àánú Jèhófà. Nínú àkàwé kan tí Jésù ṣe, ó sọ̀rọ̀ nípa ẹrú kan tó jẹ ọ̀gá ẹ̀ ní gbèsè ńlá tí ò lè san pa dà, àmọ́ ọ̀gá náà fagi lé gbogbo gbèsè yẹn. Ṣùgbọ́n, ẹrú tí wọ́n dárí jì yẹn ò dárí ji ẹrú míì tó jẹ ẹ́ ní owó tó kéré. (Mát. 18:​23-35) Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fẹ́ ká kọ́? Tá a bá mọyì àánú tí Jèhófà ń fi hàn sí wa lóòótọ́, àwa náà máa dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá. (Sm. 103:9) Ilé Ìṣọ́ kan sọ pé: “Kò sí iye ìgbà tá a dárí ji àwọn èèyàn tá a lè fi wé iye ìgbà tí Jèhófà ti dárí jì wá, tó sì fàánú hàn sí wa nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi.” Jèhófà máa dárí ji àwọn tó bá ń dárí jini. Jèhófà máa ń fàánú hàn sáwọn tó bá ń ṣàánú àwọn ẹlòmíì. (Mát. 5:7) Jésù jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà tó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà.—Mát. 6:​14, 15. w22.06 10 ¶8-9

Tuesday, June 11

Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé yóò gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ ọmọ rẹ.—Jẹ́n. 22:18.

Nígbà tí Jésù wá sáyé, àwọn nǹkan tó ṣe fi hàn pé ó fìwà jọ Bàbá rẹ̀. (Jòh. 14:9) Torí náà, àwọn nǹkan tá a kọ́ nípa Jésù ló jẹ́ ká mọ Jèhófà ká sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, à ń jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wa àti bó ṣe ń tọ́ wa sọ́nà nínú ìjọ lónìí. Ó tún ń jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó yẹ ká ṣe, kí inú Jèhófà lè dùn sí wa. Gbogbo wa tún ń jàǹfààní ikú Jésù. Lẹ́yìn tí Jèhófà jí i dìde, ó gba ẹbọ pípé tí Jésù rú láti “wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.” (1 Jòh. 1:7) Ó ti di Ọba tá a ṣe lógo lọ́run, kò sì lè kú mọ́. Láìpẹ́, Jésù máa fọ́ orí Èṣù túútúú. (Jẹ́n. 3:15) Ẹ ò rí i pé ìtura máa dé bá àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ nígbà tí Sátánì bá pa run! Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, má jẹ́ kó sú ẹ torí pé Ọlọ́run wa ṣeé fọkàn tán. Ó máa ṣe ọ̀pọ̀ ohun rere fún “gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé.” w22.07 18 ¶13; 19 ¶19

Wednesday, June 12

Kò sí bí a ò ṣe ní jìyà irú àwọn nǹkan yìí.—1 Tẹs. 3:3.

Tá a bá fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ ní ju àfojúsùn kan ṣoṣo lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé nǹkan lè má rí bá a ṣe rò. Wo àpẹẹrẹ yìí ná: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣèrànwọ́ láti dá ìjọ sílẹ̀ nílùú Tẹsalóníkà. Àmọ́ àwọn alátakò lé Pọ́ọ̀lù kúrò nílùú náà. (Ìṣe 17:​1-5, 10) Ká sọ pé Pọ́ọ̀lù ò kúrò níbẹ̀ ni, á fi ẹ̀mí àwọn ará wewu. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ṣì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe nípò tó bá ara ẹ̀. Nígbà tó yá, ó ní kí Tímótì lọ sí Tẹsalóníkà kó lè ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni lọ́wọ́. (1 Tẹs. 3:​1, 2) Ó dájú pé inú àwọn ará Tẹsalóníkà dùn gan-an. Àwa náà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù nílùú Tẹsalóníkà. A lè ní iṣẹ́ ìsìn kan lọ́kàn tá a fẹ́ ṣe, àmọ́ nígbà tí ipò wa yí pa dà, ọwọ́ wa ò lè tẹ̀ ẹ́. (Oníw. 9:11) Tó bá jẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ nìyẹn, ńṣe ni kó o wá iṣẹ́ ìsìn míì tó o lè ṣe. w22.04 25-26 ¶14-15

Thursday, June 13

Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fara da àdánwò.—Jém. 1:12.

Jèhófà ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tù wá nínú, ó sì jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ẹ jẹ́ ká gbé kókó díẹ̀ yẹ̀ wò nínú Bíbélì tó lè tù wá nínú nígbà àdánwò. Nínú Bíbélì, Jèhófà fi dá wa lójú pé kò sí ohunkóhun títí kan àdánwò tó le gan-an tó “máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́” rẹ̀. (Róòmù 8:​38, 39) Ó tún fi dá wa lójú pé òun ‘wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń gbàdúrà sí òun.’ (Sm. 145:18) Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé òun, àá lè fara da àdánwò èyíkéyìí tó bá dé bá wa. Kódà, àá máa láyọ̀ tí ìṣòro bá tiẹ̀ ń bá wa fínra. (1 Kọ́r. 10:13; Jém. 1:2) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn àdánwò tá à ń dojú kọ báyìí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, àkókò náà ò sì tó nǹkan kan tá a bá fi wé ìyè àìnípẹ̀kun tí Ọlọ́run máa fún wa lọ́jọ́ iwájú. (2 Kọ́r. 4:​16-18) Bákan náà, Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa pa gbogbo àwọn tó ń fa àdánwò tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa run, ìyẹn Sátánì Èṣù àtàwọn ẹni burúkú tí wọ́n ń hùwà bíi tiẹ̀. (Sm. 37:10) Àmọ́, ṣé o ti mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí tó máa jẹ́ kó o lè fara da àwọn àdánwò tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú? w22.08 11 ¶11

Friday, June 14

Ẹ máa ronú lórí àwọn nǹkan yìí.—Fílí. 4:8.

Ṣé o máa ń bẹ̀rù pé o ò ní lè tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ? Jèhófà ṣèlérí pé òdodo wa máa “dà bí ìgbì òkun.” (Àìsá. 48:18) Jẹ́ ká sọ pé o wà létí òkun kan tí ìgbì òkun ń lọ, tó sì ń bọ̀ láìdáwọ́ dúró. Bó o ṣe dúró síbẹ̀, ṣé wàá máa ronú pé ìgbì náà máa dáwọ́ dúró lọ́jọ́ kan? Rárá o! Ìdí ni pé o mọ̀ pé kò ní yéé ru gùdù. Òdodo tìẹ náà lè dà bí ìgbì òkun yẹn. Lọ́nà wo? Kó o tó ṣèpinnu, kọ́kọ́ ronú nípa nǹkan tí Jèhófà máa fẹ́ kó o ṣe. Tó o bá ti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe, ṣe nǹkan náà. Kò sí bí ìpinnu náà ṣe le tó, máa rántí pé Jèhófà Bàbá ẹ onífẹ̀ẹ́ ò ní fi ẹ́ sílẹ̀, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀ lójoojúmọ́.—Àìsá. 40:​29-31. w22.08 30 ¶15-17

Saturday, June 15

Gbàrà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà bá parí, a máa tú Sátánì sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n rẹ̀.—Ìfi. 20:7.

Lẹ́yìn tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá parí, Jèhófà máa tú Sátánì sílẹ̀. Á wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbìyànjú láti ṣi àwọn èèyàn pípé lọ́nà. Lásìkò ìdánwò yẹn, gbogbo àwọn èèyàn pípé ló máa láǹfààní láti fi hàn bóyá Jèhófà ni wọ́n fẹ́ kó máa ṣàkóso wọn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (Ìfi. 20:​8-10) Ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ṣe ló máa pinnu bóyá orúkọ wọn máa wà nínú ìwé ìyè títí láé àbí kò ní sí níbẹ̀. Bíbélì sọ pé àwọn kan máa jẹ́ aláìṣòótọ́ bíi ti Ádámù àti Éfà, wọn ò sì ní fara mọ́ àkóso Jèhófà. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn? Ìfihàn 20:15 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ní: “A ju ẹnikẹ́ni tí a kò rí i pé wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè sínú adágún iná náà.” Àbẹ́ ò rí nǹkan, gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí ló máa pa run yán-án yán-án. Àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn pípé máa yege ìdánwò ìkẹyìn. w22.09 23-24 ¶15-16

Sunday, June 16

Láìjẹ́ pé ẹ dádọ̀dọ́ gẹ́gẹ́ bí àṣà tí Mósè fi lélẹ̀, ẹ ò lè rí ìgbàlà.—Ìṣe 15:1.

Àwọn kan lára àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ń rin kinkin mọ́ ọn pé dandan ni kí àwọn Kèfèrí tó di Kristẹni dádọ̀dọ́, káwọn Júù má bàa sọ̀rọ̀ wọn láìdáa. (Gál. 6:12) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò fara mọ́ èrò wọn rárá, àmọ́ kò sọ pé dandan ni kí wọ́n fara mọ́ èrò tòun. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ní kí wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù láti yanjú ọ̀rọ̀ náà, èyí sì fi hàn pé onírẹ̀lẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 15:2) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ yìí mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ, inú àwọn ará sì ń dùn. (Ìṣe 15:​30, 31) Tí èdèkòyédè bá wáyé, a lè fi hàn pé a jẹ́ ẹni àlàáfíà tá a bá jẹ́ káwọn tí Jèhófà ní kó máa bójú tó wa tọ́ wa sọ́nà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ètò Ọlọ́run máa ń lo Bíbélì láti tọ́ wa sọ́nà, àwọn ìtọ́sọ́nà náà sì máa ń wà nínú ìwé àtàwọn ìlànà tí wọ́n ń fún wa. Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà tí wọ́n ń fún wa yìí, a ò ní máa rin kinkin mọ́ èrò wa, ìyẹn sì máa jẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ìjọ. w22.08 22 ¶8-9

Monday, June 17

Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo.—Òwe 17:17.

Nígbà míì, ó lè gba pé ká sọ ohun tó ń ṣe wá fún ẹnì kan tá a jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kára lè tù wá. Ká sòótọ́, kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Ó lè má mọ́ wa lára láti máa sọ̀rọ̀ àṣírí wa fún ẹnikẹ́ni torí a mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ náà fún ẹlòmíì, ìyẹn sì máa dùn wá gan-an. Àmọ́, a máa ń mọyì ọ̀rẹ́ tòótọ́ tó lè pa àṣírí mọ́. Àwọn alàgbà tó máa ń pa àṣírí àwọn ará ìjọ mọ́ dà bí “ibi tó ṣeé fara pa mọ́ sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù [àti] ibi ààbò.” (Àìsá. 32:2) Kò sí nǹkan tá ò lè bá wọn sọ torí a mọ̀ pé wọ́n máa ń pa àṣírí mọ́. Kò yẹ ká máa fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n sọ̀rọ̀ àṣírí fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, a mọyì ìyàwó àwọn alàgbà wa torí wọn kì í lọ́ ọkọ wọn nífun kí wọ́n lè sọ̀rọ̀ àṣírí fún wọn. Ká sòótọ́, ara máa tu ìyàwó alàgbà tí ọkọ ẹ̀ ò bá sọ̀rọ̀ àṣírí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin fún un. w22.09 11 ¶10-11

Tuesday, June 18

Èmi ni Ọlọ́run. A ó gbé mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.—Sm. 46:10.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa gba àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ sílẹ̀ nígbà “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀. (Mát. 24:21; Dán. 12:1) Jèhófà máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tí Bíbélì pè ní Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá gbéjà ko àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Kódà, tí gbogbo igba ó dín méje (193) orílẹ̀-èdè tó wà nínú Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé bá wà lára àwọn tó kóra jọ láti gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run, wọn ò ní lè kojú Ẹni Tó Lágbára Jù Lọ àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀! Jèhófà ṣèlérí pé: “Ó dájú pé màá gbé ara mi ga, màá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni mí, màá sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ irú ẹni tí mo jẹ́; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” (Ìsík. 38:​14-16, 23) Nígbà tí Gọ́ọ̀gù bá gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run, ìyẹn máa jẹ́ kí Jèhófà ja ogun àjàkẹ́yìn ní Amágẹ́dọ́nì, ó sì máa pa “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” run. (Ìfi. 16:​14, 16; 19:​19-21) Àmọ́, “àwọn adúróṣinṣin ló máa gbé ní ayé, àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ ló sì máa ṣẹ́ kù sínú rẹ̀.”—Òwe 2:​21, àlàyé ìsàlẹ̀. w22.10 16-17 ¶16-17

Wednesday, June 19

[Ọlọ́run] fẹ́ ká gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.—1 Tím. 2:4.

A ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn, torí pé ‘Jèhófà nìkan ló máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn.’ (Òwe 16:2) Gbogbo èèyàn ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ láìka ibi tí wọ́n ti wá sí àti àṣà ìbílẹ̀ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún gbà wá níyànjú pé ká “ṣí ọkàn [wa] sílẹ̀ pátápátá.” (2 Kọ́r. 6:13) Lọ́nà kan náà, gbogbo àwọn ará wa ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́, kò yẹ ká máa dá wọn lẹ́jọ́. Kì í ṣe àwọn ará nìkan ni kò yẹ ká máa dá lẹ́jọ́, kò tún yẹ ká máa dá àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́jọ́. Ṣé o máa ń dá àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́jọ́, kó o wá máa sọ pé, “Ọkùnrin yẹn ò lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láé?” Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ torí ìyẹn máa fi hàn pé o ti ń kọjá àyè ẹ, o sì ń ṣe òdodo àṣelékè. Ìdí sì ni pé Jèhófà ṣì ń “fún gbogbo èèyàn níbi gbogbo” láyé ní àǹfààní láti ronú pìwà dà. (Ìṣe 17:30) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé lójú Jèhófà, aláìṣòdodo làwọn tó bá ń ṣe òdodo àṣelékè. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà òdodo Jèhófà, inú wa máa dùn, àá sì di àpẹẹrẹ rere fáwọn èèyàn. Kódà, á mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa, kí wọ́n sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà náà. w22.08 31 ¶20-22

Thursday, June 20

Ó dájú pé wọ́n á mọ̀ pé wòlíì kan wà láàárín wọn.—Ìsík. 2:5.

Kì í yà wá lẹ́nu táwọn èèyàn bá ń ta kò wá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àtakò náà sì lè burú jùyẹn lọ lọ́jọ́ iwájú. (Dán. 11:44; 2 Tím. 3:12; Ìfi. 16:21) Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti máa ń ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ tó bá gbéṣẹ́ fún wọn, kódà tí iṣẹ́ náà bá tiẹ̀ le gan-an. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ wòlíì Ìsíkíẹ́lì, ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó lọ jíṣẹ́ fáwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì. Irú àwọn èèyàn wo ni Jèhófà sọ pé kí Ìsíkíẹ́lì lọ jíṣẹ́ fún? Jèhófà sọ pé wọ́n jẹ́ “aláìgbọràn,” “ọlọ́kàn líle” àti “ọlọ̀tẹ̀.” Wọ́n lè ṣeni léṣe bí ẹ̀gún àti òṣùṣú, wọ́n sì burú bí àkekèé. Abájọ tí Jèhófà fi sọ fún Ìsíkíẹ́lì léraléra pé: “Má bẹ̀rù”! (Ìsík. 2:​3-6) Ohun tó jẹ́ kí Ìsíkíẹ́lì lè jíṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un ni pé (1) Jèhófà ló rán an, (2) Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn án lọ́wọ́ àti (3) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ túbọ̀ lágbára. w22.11 2 ¶1-2

Friday, June 21

Ó dájú pé ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ lo máa kú.—Jẹ́n. 2:17.

Nígbà tí Jèhófà ń dá àwọn ohun alààyè sáyé, àwa èèyàn nìkan ló dá pé ká wà láàyè títí láé. Ó dá wa lọ́nà tá ò fi ní kú. Jèhófà tún dá wa lọ́nà tó fi jẹ́ pé kì í wù wá pé ká kú. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ti “fi ayérayé sí [wa] lọ́kàn.” (Oníw. 3:11) Ìdí nìyẹn tá a fi gbà pé ọ̀tá wa ni ikú. (1 Kọ́r. 15:26) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń ṣàìsàn kan tó le, ṣé àá máa wo ara wa níran títí tá a fi máa kú? Rárá. Ó dájú pé a máa lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà, àá sì lo àwọn oògùn tí wọ́n bá fún wa kí àìsàn náà lè lọ. Kódà, gbogbo nǹkan tó bá gbà la máa ṣe ká má bàa kú. Tẹ́nì kan tá a fẹ́ràn bá sì kú, bóyá ọmọdé ni tàbí àgbàlagbà, ó ṣì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Jòh. 11:​32, 33) Ó dájú pé Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ ò ní fi sí wa lọ́kàn pé ká wà láàyè títí láé tóun fúnra ẹ̀ ò bá fẹ́ ká wà láàyè títí láé. w22.12 3 ¶5; 4 ¶7

Saturday, June 22

Ẹ mọ̀ pé irú ìyà kan náà ló ń jẹ gbogbo àwọn ará yín nínú ayé.—1 Pét. 5:9.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará wa lè ṣàìsàn, ẹ̀rù lè bà wọ́n, ó sì lè ṣe wọ́n bíi pé àwọn dá wà lásìkò tí nǹkan nira yìí. Torí náà, máa bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ sọ̀rọ̀. Tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀, ó lè gba pé ká má sún mọ́ àwọn èèyàn jù, títí kan àwọn ará wa. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ó lè ṣe wá bó ṣe ṣe àpọ́sítélì Jòhánù. Ó wù ú pé kó rí Gáyọ́sì ọ̀rẹ́ ẹ̀ lójúkojú. (3 Jòh. 13, 14) Àmọ́ Jòhánù rí i pé kò ní ṣeé ṣe fóun láti rí Gáyọ́sì lásìkò yẹn. Kò sóhun tí Jòhánù lè ṣe ju pé kó kọ lẹ́tà sí i. Torí náà, tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti lọ kí àwọn ará nílé, kàn sí wọn láwọn ọ̀nà míì. Tó o bá ń bá àwọn ará sọ̀rọ̀ déédéé, kò ní máa ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà, ọkàn ẹ á sì balẹ̀. Bá àwọn alàgbà sọ̀rọ̀ tó o bá ń ṣàníyàn, kó o sì gba ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ẹ.—Àìsá. 32:​1, 2. w22.12 17-18 ¶6-7

Sunday, June 23

Ọ̀gá Jósẹ́fù ju Jósẹ́fù sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí wọ́n ń kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí.—Jẹ́n. 39:20.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà kan wà tí wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ẹsẹ̀ Jósẹ́fù, tí wọ́n sì fi irin de ọrùn rẹ̀. (Sm. 105:​17, 18) Ẹ ò rí i pé ipò tí Jósẹ́fù wà ń burú sí i ni. Ẹrú tí wọ́n fọkàn tán tẹ́lẹ̀ ti wá di ẹlẹ́wọ̀n báyìí. Ṣé o ní ìṣòro kan tó ń burú sí i, bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ò dákẹ́ àdúrà lórí ẹ̀? Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀. Jèhófà lè fàyè gba pé káwọn ìṣòro kan dé bá wa nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí. (1 Jòh. 5:19) Àmọ́ ohun kan dájú, Jèhófà mọ gbogbo ohun tójú ẹ ń rí, ó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ. (Mát. 10:​29-31; 1 Pét. 5:​6, 7) Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣèlérí pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.” (Héb. 13:5) Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da ìṣòro ẹ, tó bá tiẹ̀ dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ. w23.01 16 ¶7-8

Monday, June 24

Ọlọ́run wa . . . máa ń dárí jini fàlàlà.—Àìsá. 55:7.

Bíbélì fi dá wa lójú pé tá a bá ṣàṣìṣe, Ọlọ́run ò ní pa wá tì. Bí àpẹẹrẹ, léraléra làwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà, àmọ́ tí wọ́n bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà máa ń dárí jì wọ́n. Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ náà mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn gan-an. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti gba àwọn tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run níyànjú pé kí wọ́n ‘dárí ji’ ọkùnrin kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, àmọ́ tó ronú pìwà dà, ó sì ní kí wọ́n “tù ú nínú.” (2 Kọ́r. 2:​6, 7; 1 Kọ́r. 5:​1-5) Inú wa mà dùn o pé Jèhófà kì í pa àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ tì tá a bá ṣẹ̀ ẹ́! Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń ràn wá lọ́wọ́, ó máa ń fìfẹ́ bá wa wí, ó sì máa ń jẹ́ ká pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun. Lónìí, ìlérí yìí kan náà ni Jèhófà ṣe fún àwọn tó bá ṣẹ̀ ẹ́, àmọ́ tí wọ́n ronú pìwà dà tọkàntọkàn. (Jém. 4:​8-10) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run, onídàájọ́ òdodo ni, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa. Ìwé yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká mọ òun, ká sì di ọ̀rẹ́ òun. w23.02 7 ¶16-17

Tuesday, June 25

Ẹ̀ ń ṣe dáadáa bí ẹ ṣe ń fiyè sí i.—2 Pét. 1:19.

Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí jẹ́ ká rí i pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ. Ìdí pàtàkì sì wà tó fi yẹ kó máa wù wá láti mọ̀ nípa ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jésù jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan táá máa ṣẹlẹ̀ tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé ayé burúkú Sátánì yìí máa tó pa run. (Mát. 24:​3-14) Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi gbà wá níyànjú pé ká máa fiyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń ṣẹ, kí ìgbàgbọ́ wa lè túbọ̀ lágbára. (2 Pét. 1:​20, 21) Ó fẹ́ ká ní èrò tó tọ́ tá a bá ń ka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ó gbà wá níyànjú pé ká máa fi ‘ìgbà tí ọjọ́ Jèhófà máa wà níhìn-ín sọ́kàn dáadáa.’ (2 Pét. 3:​11-13) Kí nìdí? Kì í ṣe torí pé a fẹ́ mọ “ọjọ́ àti wákàtí” tí Jèhófà máa ja ogun Amágẹ́dọ́nì, àmọ́ ìdí tá a ṣe ń fi ọjọ́ yẹn sọ́kàn ni pé a fẹ́ lo ìwọ̀nba àkókò tó ṣẹ́ kù láti máa ‘hùwà mímọ́, ká sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.’ (Mát. 24:36; Lúùkù 12:40) A fẹ́ máa hùwà tó dáa, ká sì rí i pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló ń mú ká ṣe gbogbo ohun tá à ń ṣe. Àmọ́ ká tó lè máa ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa kíyè sí ara wa. w23.02 16 ¶4, 6

Wednesday, June 26

Mo ní àwọn àgùntàn mìíràn . . . mo gbọ́dọ̀ mú àwọn yẹn náà wá.— Jòh. 10:16.

Àwọn nǹkan kan wà tí “àwọn àgùntàn mìíràn” gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó lè gbé inú Párádísè. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jésù bá a ṣe ń ṣohun tó dáa sáwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin rẹ̀. Jésù sọ pé ohun táwọn tó fìwà jọ àgùntàn bá ṣe sáwọn arákùnrin òun lòun máa fi ṣèdájọ́ wọn. (Mát. 25:​31-40) Ọ̀kan lára ohun tá a lè ṣe ni pé ká máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:​18-20) Kò yẹ ká dúró dìgbà tá a bá dénú Párádísè ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tí Jèhófà fẹ́ ká máa hù níbẹ̀. Ìsinsìnyí ló yẹ ká ti jẹ́ olóòótọ́ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, ká má sì ṣàṣejù nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe. Ó yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ọkọ tàbí aya wa àtàwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run nínú ayé burúkú yìí, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà yẹn nínú Párádísè. Bákan náà, a lè kọ́ iṣẹ́ tá a fẹ́ ṣe nínú ayé tuntun, ká sì máa hùwà tó fi hàn pé a ti múra tán láti gbébẹ̀. w22.12 11-12 ¶14-16

Thursday, June 27

Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ mi, Baba mi máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Jòh. 14:21.

Inú wa ń dùn pé Jésù ni Ọba wa torí òun ni Alákòóso tó dáa jù lọ. Jèhófà fúnra ẹ̀ ló dá Jésù lẹ́kọ̀ọ́ tó sì ní kó máa ṣàkóso. (Àìsá. 50:​4, 5) Tún ronú nípa bí Jésù ṣe fi ẹ̀mí ara ẹ̀ rúbọ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Jòh. 13:1) Jésù ni Ọba wa, torí náà, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Ó ṣàlàyé pé àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ òun máa ń pa àṣẹ òun mọ́, ó sì sọ pé ọ̀rẹ́ òun ni wọ́n. (Jòh. 14:15; 15:​14, 15) Ẹ ò rí i pé Jèhófà dá wa lọ́lá gan-an torí pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọmọ ẹ̀! O mọ̀ pé ẹni pípé ni Jésù, ó nírẹ̀lẹ̀, ó sì fìwà jọ Bàbá ẹ̀. O tún mọ̀ pé Jésù bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó tu àwọn èèyàn nínú, ó sì mú àwọn aláìsàn lára dá. (Mát. 14:​14-21) Yàtọ̀ síyẹn, ò ń rí bó ṣe ń darí ìjọ Kristẹni lónìí. (Mát. 23:10) O sì mọ̀ pé òun ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run tó máa ṣe ọ̀pọ̀ ohun rere fún wa lọ́jọ́ iwájú. Báwo lo ṣe máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jésù? Bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa fara wé e. Ohun tó o máa kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó o sì ṣèrìbọmi. w23.03 4 ¶8, 10

Friday, June 28

Ẹ gbé ojú yín sókè ọ̀run, kí ẹ sì wò ó. Ta ló dá àwọn nǹkan yìí?—Àìsá. 40:26.

Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan tó wà lọ́run àti ayé títí kan àwọn nǹkan tó wà nínú òkun, àwọn nǹkan yìí sì ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́. (Sm. 104:​24, 25) Tún ronú nípa bí Jèhófà ṣe dá àwa èèyàn. Tá a bá rí àwọn nǹkan tó rẹwà, a máa ń mọyì ẹ̀ gan-an. Jèhófà dá wa ká lè máa ríran, ká máa gbọ́ràn, ká mọ nǹkan lára, ká mọ adùn nǹkan, ká sì lè gbóòórùn. Àwọn nǹkan yìí ló ń jẹ́ ká gbádùn oríṣiríṣi nǹkan tí Jèhófà dá. Bíbélì tún sọ ìdí pàtàkì míì tó fi yẹ ká máa kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Àwọn nǹkan náà ń jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní. (Róòmù 1:20) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, àá rí i pé onírúurú wọn ló wà, àgbàyanu sì ni wọ́n. Ṣé àwọn nǹkan yẹn ò fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run? Tún ronú nípa onírúurú oúnjẹ tá à ń gbádùn. Àwọn oúnjẹ yẹn jẹ́ ká rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Tá a bá ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, tíyẹn sì ń jẹ́ ká rí àwọn ànímọ́ tó ní, á jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́ ká sì sún mọ́ ọn. w23.03 16 ¶4-5

Saturday, June 29

Òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ.—Sm. 119:160.

Bí ayé yìí ṣe ń burú sí i, àwọn nǹkan kan máa dán wa wò bóyá a gbà pé òótọ́ lohun tó wà nínú Bíbélì. Àwọn kan lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì. Wọ́n lè fẹ́ ká máa ṣiyèméjì pé ṣé òótọ́ lohun tó wà nínú Bíbélì àti pé ṣé òótọ́ ni Jèhófà yan ẹrú olóòótọ́ àti olóye pé kó máa darí àwa èèyàn ẹ̀ lónìí? Àmọ́ tó bá dá wa lójú pé òtítọ́ ni Ọ̀rọ̀ Jèhófà, irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ní mi ìgbàgbọ́ wa. A máa ‘pinnu láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nígbà gbogbo, àá sì ṣe bẹ́ẹ̀ délẹ̀délẹ̀.’ (Sm. 119:112) A ò “ní tijú” láti sọ òtítọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn, àá sì gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa fi sílò. (Sm. 119:46) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àá lè fara da àwọn ìṣòro tí ò rọrùn títí kan inúnibíni, àá sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ “pẹ̀lú sùúrù àti ìdùnnú.” (Kól. 1:11; Sm. 119:​143, 157) Òtítọ́ yìí ń fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó sì ń jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká fi ayé wa ṣe. Ó tún ń jẹ́ ká nírètí pé ọjọ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso. w23.01 7 ¶16-17

Sunday, June 30

Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín.—Jòh. 13:34.

Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, àkókò tó fi gbàdúrà nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ gùn gan-an, ó sì sọ fún Bàbá ẹ̀ pé “kí o máa ṣọ́ wọn torí ẹni burúkú náà.” (Jòh. 17:15) Ẹ ò rí i pé Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ gan-an! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù máa tó dojú kọ àdánwò tó lágbára gan-an, bó ṣe máa bójú tó àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ ló gbà á lọ́kàn. Bíi ti Jésù, kì í ṣe tara wa nìkan ló yẹ ká gbájú mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nígbà gbogbo. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa, Jèhófà náà á sì rí i pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa lóòótọ́. A ò fi àkókò wa ṣòfò tá a bá ń gbàdúrà fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa torí Bíbélì sọ pé “ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo lágbára gan-an.” (Jém. 5:16) Torí náà, ó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn ará wa torí pé wọ́n ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro. w22.07 23-24 ¶13-15

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́