ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es24 ojú ìwé 67-77
  • July

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Monday, July 1
  • Tuesday, July 2
  • Wednesday, July 3
  • Thursday, July 4
  • Friday, July 5
  • Saturday, July 6
  • Sunday, July 7
  • Monday, July 8
  • Tuesday, July 9
  • Wednesday, July 10
  • Thursday, July 11
  • Friday, July 12
  • Saturday, July 13
  • Sunday, July 14
  • Monday, July 15
  • Tuesday, July 16
  • Wednesday, July 17
  • Thursday, July 18
  • Friday, July 19
  • Saturday, July 20
  • Sunday, July 21
  • Monday, July 22
  • Tuesday, July 23
  • Wednesday, July 24
  • Thursday, July 25
  • Friday, July 26
  • Saturday, July 27
  • Sunday, July 28
  • Monday, July 29
  • Tuesday, July 30
  • Wednesday, July 31
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
es24 ojú ìwé 67-77

July

Monday, July 1

Jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn olóòótọ́ nínú ọ̀rọ̀.—1 Tím. 4:12.

Jèhófà Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ ló fún wa lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ. Àmọ́ àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí ò dáa. Sátánì parọ́ fún Éfà, irọ́ tó pa yìí ló mú káwa èèyàn di ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé. (Jẹ́n. 3:​1-4) Nígbà tí Ádámù ṣàṣìṣe, ó sọ ohun tí ò dáa torí ó dá Éfà àti Jèhófà lẹ́bi fún ohun tó ṣe. (Jẹ́n. 3:12) Kéènì náà parọ́ fún Jèhófà lẹ́yìn tó pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀. (Jẹ́n. 4:9) Bákan náà lónìí, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn fíìmù táwọn èèyàn ń ṣe jáde ni wọ́n ti máa ń sọ̀sọkúsọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọmọ iléèwé máa ń gbọ́ táwọn èèyàn ń sọ̀sọkúsọ nílé ìwé wọn, àwọn àgbàlagbà náà sì máa ń dojú kọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ níbiiṣẹ́. Tá ò bá kíyè sára, àwa náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀sọkúsọ bíi tàwọn tó wà láyìíká wa. Torí pé Kristẹni ni wá, a fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú Jèhófà dùn, èyí sì gba pé ká yẹra fún ìsọkúsọ. A fẹ́ lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Jèhófà fún wa láti máa fi yìn ín. w22.04 4 ¶1-3

Tuesday, July 2

Ẹ ò lè sin Ọlọ́run àti Ọrọ̀.—Mát. 6:24.

Ojú tó tọ́ ni Jésù fi wo àwọn nǹkan tara. Ó máa ń gbádùn oúnjẹ àti ohun mímu. (Lúùkù 19:​2, 6, 7) Ìgbà kan wà tó ṣe wáìnì tó dáa gan-an, kódà iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tó ṣe nìyẹn. (Jòh. 2:​10, 11) Lọ́jọ́ tó sì kú, aṣọ olówó ńlá ló wọ̀. (Jòh. 19:​23, 24) Àmọ́ kì í ṣe àwọn nǹkan tara yẹn ni Jésù gbájú mọ́. Jésù kọ́ wa pé tá a bá ń wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́, Ọlọ́run máa pèsè ohun tá a nílò fún wa. (Mát. 6:​31-33) Ọ̀pọ̀ ló ti jàǹfààní torí pé wọ́n ń lo ọgbọ́n Ọlọ́run tó bá dọ̀rọ̀ owó. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tí kò tíì gbéyàwó tó ń jẹ́ Daniel. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, mo pinnu pé ìjọsìn Jèhófà ló máa gbawájú láyé mi.” Torí pé Daniel jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn, ó ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì, ó sì máa ń yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti ran àwọn tí àjálù dé bá lọ́wọ́. Ó tún sọ pé: “Kò sí owó tó lè ra àwọn ohun rere tí Jèhófà ti fún mi.” w22.05 21-22 ¶6-7

Wednesday, July 3

[Jèhófà] pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.—1 Pét. 2:9.

Bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Kódà, tá a bá tiẹ̀ ti pẹ́ nínú òtítọ́, ó yẹ ká ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Ó gba iṣẹ́ àṣekára kéèyàn tó lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ó lérè. Gbogbo wa kọ́ ló máa ń wù pé ká kàwé tàbí ká dá kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ Jèhófà rọ̀ wá pé ká máa “wá” òtítọ́ kiri ká lè mọ òtítọ́. (Òwe 2:​4-6) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa jàǹfààní gan-an. Arákùnrin Corey sọ pé tóun bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹsẹ Bíbélì kan lòun máa ń gbájú mọ́. Ó ṣàlàyé pé: “Mo máa ń ka àlàyé ìsàlẹ̀ ẹsẹ Bíbélì náà, màá wo àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tá a tọ́ka sí, màá sì ṣèwádìí ẹ̀. . . . Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo máa ń rí kọ́ torí pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà yìí!” Tá a bá ń lo okun àti àkókò wa láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́nà yìí tàbí láwọn ọ̀nà míì, á fi hàn pé a mọyì òtítọ́ gan-an.—Sm. 1:​1-3. w22.08 17 ¶13; 18 ¶15-16

Thursday, July 4

Mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́. Èmi ni àrídunnú rẹ̀ lójoojúmọ́; inú mi sì ń dùn níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.—Òwe 8:30.

Nígbà tí Jésù wá sáyé, ó fi àwọn nǹkan tí Bàbá rẹ̀ dá kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀kan lára ohun tó kọ́ wọn. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn. Nínú Ìwàásù orí Òkè, Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun kíyè sí méjì lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá táwọn èèyàn kì í kíyè sí. Àwọn nǹkan méjì náà ni oòrùn àti òjò. Àwọn nǹkan méjì yìí ṣe pàtàkì torí pé wọ́n ń gbé ẹ̀mí wa ró. Jèhófà lè sọ pé kí oòrùn má ràn, kí òjò má sì rọ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ò sin òun, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo èèyàn pátá ló ń jàǹfààní àwọn nǹkan yìí. (Mát. 5:​43-45) Jésù lo àwọn ohun tí Jèhófà dá yìí láti fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn. Nígbàkigbà tá a bá rí oòrùn tó rẹwà tó ń wọ̀ tàbí tí òjò tó tuni lára ń rọ̀, wọ́n máa ń rán wa létí pé Jèhófà kì í ṣojúsàájú. Táwa náà bá ń fara wé Jèhófà, tá à ń wàásù fún gbogbo èèyàn, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn nìyẹn. w23.03 17 ¶9-10

Friday, July 5

Ó yà mí lẹ́nu gan-an.—Ìfi. 17:6.

Kí ló ya àpọ́sítélì Jòhánù lẹ́nu? Ó rí obìnrin kan tó ń gun ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò. Bíbélì sọ pé “aṣẹ́wó ńlá” ni, ó sì pè é ní “Bábílónì Ńlá.” Òun ni “àwọn ọba ayé” bá “ṣe ìṣekúṣe.” (Ìfi. 17:​1-5) Ta ni “Bábílónì Ńlá”? Obìnrin yẹn ò lè jẹ́ ètò òṣèlú torí Bíbélì sọ pé ó bá àwọn olórí olóṣèlú ayé ṣe ìṣekúṣe. (Ìfi. 18:9) Kódà, ó máa ń darí àwọn alákòóso, ìyẹn ni pé ó ń gùn wọ́n. Bákan náà, kò lè jẹ́ ètò ìṣòwò jẹgúdújẹrá ayé yìí. Ìdí ni pé ètò ìṣòwò ni Bíbélì pè ní “àwọn oníṣòwò ayé.” (Ìfi. 18:​11, 15, 16) Ìlú Bábílónì àtijọ́ ni ojúkò ìjọsìn èké nígbà yẹn. Torí náà, Bábílónì Ńlá ní láti ṣàpẹẹrẹ gbogbo ìjọsìn èké. Kódà, òun ni àpapọ̀ gbogbo ẹ̀sìn èké ayé.—Ìfi. 17:​5, 18. w22.05 11 ¶14-16

Saturday, July 6

Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá yín ń rìn káàkiri bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù, ó ń wá bó ṣe máa pani jẹ.—1 Pét. 5:8.

Ọkàn àwọn ìyá kì í balẹ̀ torí wọn ò mọ̀ bóyá àwọn ọmọ wọn á sin Jèhófà. Ó ṣe tán, àwọn òbí mọ̀ pé oríṣiríṣi nǹkan làwọn ọmọ wọn ń dojú kọ nínú ayé Sátánì yìí. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìyá ló ń dá tọ́mọ torí pé wọn ò lọ́kọ mọ́ tàbí torí pé ọkọ wọn ò sin Jèhófà. Inú ìdílé tí ọkọ tàbí aya kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan kọ́ ló ti ṣòro láti tọ́ àwọn ọmọ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Kódà táwọn òbí méjèèjì bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kì í rọrùn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè di olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Èyí ó wù kó jẹ́, fọkàn balẹ̀, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Á dáa kó o gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tó ti tọ́mọ yanjú kó o lè mọ bó o ṣe máa lo àwọn ìwé yìí láti kọ́ àwọn ọmọ ẹ nígbà ìjọsìn ìdílé yín. (Òwe 11:14) Jèhófà tún máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ bí wàá ṣe máa bá àwọn ọmọ ẹ sọ̀rọ̀. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè lo ìbéèrè láti mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn.—Òwe 20:5. w22.04 17 ¶4, 7; 18 ¶9

Sunday, July 7

Mò ń gbà á ládùúrà pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ pọ̀ gidigidi, kí ẹ sì ní ìmọ̀ tó péye àti òye tó kún rẹ́rẹ́.—Fílí. 1:9.

Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀ gan-an. Torí náà, tá a bá túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Héb. 1:3) Ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà mọ Jésù ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà nínú Bíbélì. Tó bá jẹ́ pé o ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì lójoojúmọ́, o ò ṣe bẹ̀rẹ̀ báyìí? Bó o ṣe ń ka ìtàn ìgbésí ayé Jésù, máa kíyè sí ìwà àti ìṣe ẹ̀. Wàá rí i pé ẹni tó ṣeé sún mọ́ ni, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé kódà ó gbé wọn sí apá rẹ̀. (Máàkù 10:​13-16) Ọkàn àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ ẹ̀, wọ́n sì máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún un. (Mát. 16:22) Àwọn nǹkan yìí ló jẹ́ ká rí i pé Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀ gan-an. Jèhófà náà sì jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, ìdí ni pé a lè gbàdúrà sí i. Kódà, kò sí nǹkan tó wà lọ́kàn wa tá ò lè sọ fún un torí ó dá wa lójú pé kò ní dá wa lẹ́bi. Ó ṣe tán, ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ń bójú tó wa.—1 Pét. 5:7. w22.08 3 ¶4-5

Monday, July 8

Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini.—Sm. 86:5.

Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, kò sóhun tí ò mọ̀ nípa wa. Ó yà wá lẹ́nu nígbà tá a mọ̀ pé Jèhófà mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa gbogbo èèyàn tó wà láyé. (Sm. 139:​15-17) Torí náà, Jèhófà mọ gbogbo àìpé tá a jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Kódà, Jèhófà mọ àwọn nǹkan tó ń mú ká ṣe àwọn ohun tá à ń ṣe. Kí làwọn nǹkan tí Jèhófà mọ̀ yìí jẹ́ kó ṣe? Ó ń mú kó fàánú hàn sí wa. (Sm. 78:39; 103:​13, 14) Jèhófà fi hàn pé òun ṣe tán láti dárí jì wá. Ó mọ̀ pé ìdí tá a fi ń dẹ́ṣẹ̀ tá a sì ń kú ni pé a ti jogún àìpé látọ̀dọ̀ Ádámù. (Róòmù 5:12) Kò sóhun tá a lè ṣe láti gba ara wa tàbí àwọn míì sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Sm. 49:​7-9) Àmọ́ torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó ṣàánú wa, ó sì ṣe ohun tó jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Jòhánù 3:16 sọ pé Jèhófà rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo kó lè kú nítorí wa.—Mát. 20:28; Róòmù 5:19. w22.06 3 ¶5-6

Tuesday, July 9

Ẹni tó ń ṣoore ń ṣe ara rẹ̀ láǹfààní.—Òwe 11:17.

Jèhófà jẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé àwọn tó bá ń fi àánú hàn, tí wọ́n sì ń dárí jini lòun máa fàánú hàn sí. Ọ̀rọ̀ burúkú táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ìyẹn Élífásì, Bílídádì àti Sófárì sọ sí i dùn ún gan-an. Àmọ́, Jèhófà sọ fún Jóòbù pé kó gbàdúrà fún wọn. Lẹ́yìn tó ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà bù kún un lọ́pọ̀lọpọ̀. (Jóòbù 42:​8-10) Tá a bá ń di àwọn èèyàn sínú, ó máa pa wá lára. Tá a bá di ẹnì kan sínú, ṣe ló dà bí ìgbà tá a di ẹrù kan tó wúwo lé ara wa lórí. Jèhófà ò sì fẹ́ kírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa. (Éfé. 4:​31, 32) Ó gbà wá níyànjú pé ká “fi ìbínú sílẹ̀, kí [a] sì pa ìrunú tì.” (Sm. 37:8) Tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, ó máa fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni wá. Tá a bá ń di àwọn èèyàn sínú, ó lè ṣàkóbá fún ìlera wa. (Òwe 14:30) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá mu omi tó ní májèlé, àwa ló máa pa lára kì í ṣe ẹlòmíì. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé tá a bá di ẹnì kan sínú, àwa ló máa pa lára kì í ṣe ẹni tó múnú bí wa. Torí náà, tá a bá dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá, ara wa là ń ṣe láǹfààní. Ọkàn wa máa balẹ̀, á sì rọrùn fún wa láti máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó. w22.06 10 ¶9-10

Wednesday, July 10

Ẹ gbé àwo ìgbàyà ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wọ̀, kí a sì dé ìrètí ìgbàlà bí akoto.—1 Tẹs. 5:8.

Ìrètí tá a ní dà bí akoto tó ń dáàbò bo èrò wa, kì í jẹ́ ká mọ tara wa nìkan kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà má bàa bà jẹ́. (1 Kọ́r. 15:​33, 34) Ìrètí tá a ní kì í jẹ́ ká ronú pé kò sí àǹfààní kankan nínú bá a ṣe ń sapá láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Ṣẹ́ ẹ rántí pé Élífásì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó pe ara wọn lọ́ọ̀rẹ́ Jóòbù sọ nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀. Élífásì sọ pé: “Kí ni ẹni kíkú jẹ́ tó fi máa mọ́?” Ó tún sọ nípa Ọlọ́run pé: “Wò ó! Kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, àwọn ọ̀run pàápàá kò mọ́ ní ojú rẹ̀.” (Jóòbù 15:​14, 15) Ẹ ò rí i pé irọ́ ńlá nìyẹn! Má gbàgbé pé Sátánì ló máa ń fẹ́ ká nírú èrò yẹn. Ó mọ̀ pé tó o bá ti ń nírú èrò bẹ́ẹ̀, ìrètí tó o ní ò ní dá ẹ lójú mọ́. Torí náà, má gba èròkerò yẹn láyè. Má ṣiyèméjì rárá torí Jèhófà fẹ́ kó o wà láàyè títí láé àti pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀ ẹ́.—1 Tím. 2:​3, 4. w22.10 25-26 ¶8-10

Thursday, July 11

Jóòbù kò fi ẹnu rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀.—Jóòbù 2:10.

Sátánì fẹ́ kí Jóòbù gbà pé ìdí tí ìyà fi ń jẹ ẹ́ ni pé Ọlọ́run ń bínú sí i. Bí àpẹẹrẹ, Sátánì mú kí ìjì tó lágbára wó ilé tí àwọn ọmọ Jóòbù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ti jọ ń jẹun. (Jóòbù 1:​18, 19) Yàtọ̀ síyẹn, ó mú kí iná sọ láti ọ̀run, ó sì jó àwọn ẹran ọ̀sìn Jóòbù títí kan àwọn ìránṣẹ́ tó ń bójú tó wọn. (Jóòbù 1:16) Torí pé kì í ṣe àwọn èèyàn ló fa ìjì àti iná yẹn, Jóòbù gbà pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá. Ìyẹn mú kó rò pé òun ti ṣẹ Jèhófà. Síbẹ̀, Jóòbù ò bú Jèhófà Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Ó gbà pé ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan rere fún òun. Torí náà, tí nǹkan tí ò dáa bá ṣẹlẹ̀ sí òun, ó yẹ kóun fara mọ́ ọn. Ó wá sọ pé: “Ká máa yin orúkọ Jèhófà títí lọ.”—Jóòbù 1:​20, 21. w22.06 21 ¶7

Friday, July 12

Gbogbo èèyàn máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Àmọ́ ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.—Máàkù 13:13.

Jésù kìlọ̀ ohun kan náà fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nínú Jòhánù 17:14. Ẹ̀rí tó dájú wà pé àsọtẹ́lẹ̀ náà ti ṣẹ, pàápàá ní ọgọ́rùn-ún ọdún (100) tó kọjá yìí. Kí ló jẹ́ ká sọ bẹ́ẹ̀? Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù di Mèsáyà Ọba lọ́dún 1914, a lé Sátánì kúrò lọ́run wá sí ayé. Ní báyìí, kò lè pa dà sọ́run mọ́, ó sì ń dúró de ìgbà tó máa pa run. (Ìfi. 12:​9, 12) Àmọ́ bó ṣe ń dúró yẹn, kò sinmi, ọwọ́ ẹ̀ dí gan-an. Inú ń bí Sátánì gan-an, ó sì ń gbógun ti àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ìfi. 12:​13, 17) Ìdí nìyẹn tí aráyé fi túbọ̀ ń kórìíra wa. Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká máa bẹ̀rù Sátánì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dá wa lójú bó ṣe dá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lójú nígbà tó sọ pé: “Tí Ọlọ́run bá wà lẹ́yìn wa, ta ló lè dènà wa?” (Róòmù 8:31) Torí náà, a lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. w22.07 18 ¶14-15

Saturday, July 13

A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.—Mát. 24:14.

Jésù ò bẹ̀rù pé àwọn tó máa ṣiṣẹ́ ìwàásù ò ní tó nǹkan ní àkókò òpin yìí. Ó mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ tí onísáàmù sọ máa ṣẹ, ó ní: “Àwọn èèyàn rẹ máa yọ̀ǹda ara wọn tinútinú ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ.” (Sm. 110:3) Tó o bá wà lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìwàásù, ìwọ náà ń ti Jésù àti ẹrú olóòótọ́ lẹ́yìn nìyẹn, o sì ń jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ sí ẹ lára. Iṣẹ́ náà ń tẹ̀ síwájú, àmọ́ à ń dojú kọ àwọn ìṣòro kan. Ọ̀kan lára ìṣòro tá à ń dojú kọ bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run ni àtakò. Àwọn apẹ̀yìndà, àwọn olórí ẹ̀sìn àtàwọn olóṣèlú ń parọ́ mọ́ wa pé iṣẹ́ ìwàásù wa ò dáa. Tí àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ bá gba irọ́ yìí gbọ́, wọ́n lè fúngun mọ́ wa pé ká má sin Jèhófà mọ́, ká má sì wàásù mọ́. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ta kò wá ni pé wọ́n máa ń halẹ̀ mọ́ wa, wọ́n ń gbéjà kò wá, wọ́n ń fi ọlọ́pàá mú wa, wọ́n sì máa ń sọ wá sẹ́wọ̀n. w22.07 8 ¶1; 9 ¶5-6

Sunday, July 14

A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ Ìjọba Ọlọ́run.—Ìṣe 14:22.

Jèhófà fẹ́ ká ní àkókò kan tá a yà sọ́tọ̀ láti máa fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, ká sì máa ronú lórí ohun tá a kà. Tá a bá ń fi àwọn ohun tá à ń kọ́ sílò, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára, àá sì túbọ̀ sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run. Ìyẹn lá sì jẹ́ ká fara da àwọn àdánwò tó lè dé bá wa. Jèhófà tún máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ran àwọn tó bá ń ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ̀mí mímọ́ yìí sì máa ń jẹ́ ká ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá,” ká lè fara da àdánwò èyíkéyìí. (2 Kọ́r. 4:​7-10) Jèhófà ń ran “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” lọ́wọ́ láti máa ṣe ìwé, fídíò àtàwọn orin tó ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, tí kò sì jẹ́ ká fi Jèhófà sílẹ̀. (Mát. 24:45) Jèhófà ti kọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. (2 Kọ́r. 1:​3, 4; 1 Tẹs. 4:9) Àwọn ará wa máa ń tètè ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ nígbà ìṣòro. w22.08 12 ¶12-14

Monday, July 15

Ẹ máa sapá lójú méjèèjì láti pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.—Éfé. 4:3.

Tá a bá ń sọ ohun tó dáa nípa àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, àá túbọ̀ sún mọ́ra wa, ìfẹ́ tó wà láàárín wa sì máa lágbára sí i. Nígbà míì, èdèkòyédè máa ń wáyé láàárín àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ nìyẹn. Nígbà tí wọ́n fẹ́ rìnrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì, àwọn méjèèjì bá ara wọn jiyàn gan-an. Ẹnì kan sọ pé kí wọ́n mú Máàkù dání, ẹnì kejì sì sọ pé kí wọ́n má mú un dání. Bíbélì sọ pé ‘àwọn méjèèjì gbaná jẹ,’ wọ́n sì pínyà. (Ìṣe 15:​37-39) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín wọn. Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó dáa nípa Bánábà àti Máàkù. (1 Kọ́r. 9:6; Kól. 4:10) Ó yẹ káwa náà máa yanjú aáwọ̀ tó bá wà láàárín àwa àtàwọn ará ìjọ wa, ká sì máa wo ibi tí wọ́n dáa sí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ, káwọn ará sì wà níṣọ̀kan. w22.08 23 ¶10-11

Tuesday, July 16

Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.—Mát. 7:1.

Bá a ṣe ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà lójoojúmọ́, kò yẹ ká máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ tàbí ká di olódodo àṣelékè. Ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà ni “Onídàájọ́ gbogbo ayé.” (Jẹ́n. 18:25) Jèhófà ò sì bẹ̀ wá níṣẹ́ pé ká máa bá òun dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù yẹ̀ wò. Kò dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ títí kan àwọn tó hùwà ìkà sí i. Àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ lù ú, wọ́n tà á sóko ẹrú, wọ́n sì jẹ́ kí bàbá wọn gbà pé ó ti kú. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, Jósẹ́fù àti ìdílé ẹ̀ tún jọ wà pa pọ̀. Lásìkò yẹn, ó ti di olórí orílẹ̀-èdè kan, torí náà ó lè sọ pé òun á fìyà jẹ àwọn ẹ̀gbọ́n òun, òun á sì gbẹ̀san lára wọn. Ẹ̀rù wá ń ba àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù pé ó lè jẹ́ nǹkan tó máa ṣe fún wọn gan-an nìyẹn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ronú pìwà dà. Àmọ́ Jósẹ́fù fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni Ọlọ́run ni?” (Jẹ́n. 37:​18-20, 27, 28, 31-35; 50:​15-21) Ìrẹ̀lẹ̀ mú kí Jósẹ́fù gbà pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti dáni lẹ́jọ́. w22.08 30 ¶18-19

Wednesday, July 17

Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó yẹ kí o ṣe é fúntó bá wà níkàáwọ́ rẹ láti ṣe é.—Òwe 3:27.

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Jèhófà lè lò ẹ́ láti dáhùn àdúrà tí ìránṣẹ́ ẹ̀ kan gbà tọkàntọkàn? Kò sẹ́ni tí ò lè lò. Bóyá alàgbà ni wá, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, aṣáájú-ọ̀nà déédéé tàbí akéde nínú ìjọ. Ó sì lè lo ọmọdé, àgbàlagbà, arákùnrin tàbí arábìnrin. Tí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bá sọ pé kó ran òun lọ́wọ́, Jèhófà máa ń lo àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láti ‘tu ẹni náà nínú.’ (Kól. 4:11) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé Jèhófà ń lò wá láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́! A sì máa ń láǹfààní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀, tí àjálù bá wáyé tàbí nígbà inúnibíni. Ó lè wù wá láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, àmọ́ ó lè má rọrùn torí pé àwa náà fẹ́ bójú tó ìdílé wa. Láìka gbogbo ìyẹn sí, ó yẹ ká ran àwọn ará wa lọ́wọ́, inú Jèhófà á sì dùn tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—Òwe 19:17. w22.12 22 ¶1-2

Thursday, July 18

Àṣẹ mi nìyí, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín.—Jòh. 15:12.

Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, wọ́n á fọkàn tán wa. Jésù sọ pé àṣẹ méjì tó tóbi jù lọ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti ọmọnìkejì wa. (Mát. 22:​37-39) A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà torí pé ó ṣeé fọkàn tán, ó sì yẹ ká fara wé e. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa náà, a máa ń pa ọ̀rọ̀ àṣírí wọn mọ́. Torí náà, kò yẹ ká sọ ohunkóhun tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn àti ìtìjú bá wọn, tó sì máa dùn wọ́n gan-an. Bákan náà, tá a bá nírẹ̀lẹ̀, àwọn èèyàn máa fọkàn tán wa. Tí Kristẹni kan bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kì í ṣe ẹnu ẹ̀ làwọn èèyàn á ti kọ́kọ́ máa gbọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí torí káwọn èèyàn lè gba tiẹ̀. (Fílí. 2:3) Kò ní máa ṣe fọ́rífọ́rí pé òun mọ ọ̀rọ̀ àṣírí táwọn ẹlòmíì ò mọ̀ tó sì jẹ́ pé kò lè sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ síta. Bákan náà, tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, a ò ní máa tan ọ̀rọ̀ kan tí ò jóòótọ́ kálẹ̀ tó sì jẹ́ pé Bíbélì àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run ò ṣàlàyé kankan nípa ẹ̀. w22.09 12 ¶12-13

Friday, July 19

Ìmọ̀ tòótọ́ sì máa pọ̀ yanturu.—Dán. 12:4.

Áńgẹ́lì kan sọ fún Dáníẹ́lì pé àwọn èèyàn Ọlọ́run máa túbọ̀ lóye àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì, àmọ́ “ kò . . . ní yé ìkankan nínú àwọn ẹni burúkú.” (Dán. 12:10) Àsìkò yìí gan-an ló yẹ kó máa hàn nínú ìwà wa pé a ò sí lára àwọn èèyàn burúkú. (Mál. 3:​16-18) Jèhófà ti ń kó àwọn tó kà sí “ohun ìní [ẹ̀] pàtàkì” jọ báyìí. Ó sì dájú pé gbogbo wa la fẹ́ wà lára wọn. Lóòótọ́, àsìkò táwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ tẹ̀ léra wọn là ń gbé yìí. Àmọ́, àwọn nǹkan àgbàyanu tó jùyẹn lọ máa tó ṣẹlẹ̀. Láìpẹ́, kò ní sí ẹnì kankan tó máa hùwà ibi mọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Dáníẹ́lì máa ṣẹ pé: “Wàá dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.” (Dán. 12:13) Ṣé ò ń retí ìgbà tí Dáníẹ́lì àtàwọn èèyàn ẹ tó ti kú máa pa dà jí “dìde”? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe gbogbo nǹkan tó o lè ṣe, kó o sì jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé orúkọ ẹ máa wà nínú ìwé ìyè títí láé. w22.09 24 ¶17; 25 ¶19-20

Saturday, July 20

Màá rán ọ.—Ìsík. 2:3.

Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí máa fún Ìsíkíẹ́lì lókun gan-an. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Ìsíkíẹ́lì rántí pé Jèhófà sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún Mósè àti Àìsáyà nígbà tó yàn wọ́n pé kí wọ́n máa ṣe wòlíì fóun. (Ẹ́kís. 3:10; Àìsá. 6:8) Ìsíkíẹ́lì tún mọ bí Jèhófà ṣe ran àwọn wòlíì méjèèjì yẹn lọ́wọ́ láti borí ìṣòro wọn. Torí náà, nígbà tí Jèhófà sọ fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì lẹ́ẹ̀mejì pé: “Màá rán ọ,” ìyẹn jẹ́ kó fọkàn tán Jèhófà pé ó máa ran òun lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì, gbólóhùn míì tún fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà pé: “Jèhófà sọ fún mi pé.” (Ìsík. 3:16) Gbólóhùn kan tún fara hàn léraléra pé “Jèhófà tún sọ fún mi pé.” (Ìsík. 6:1) Torí náà, àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ kó dá Ìsíkíẹ́lì lójú pé Jèhófà ló rán òun níṣẹ́. Ohun míì tún ni pé torí pé ọmọ àlùfáà ni Ìsíkíẹ́lì, ó ṣeé ṣe kí bàbá ẹ̀ ti sọ fún un pé Jèhófà máa ń ran àwọn wòlíì ẹ̀ lọ́wọ́. Jèhófà tún sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún Ísákì, Jékọ́bù àti Jeremáyà. Ó sọ pé: “Mo wà pẹ̀lú rẹ.”—Jẹ́n. 26:24; 28:15; Jer. 1:8. w22.11 2 ¶3

Sunday, July 21

Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 17:3.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, tí ìyẹn sì mú káwọn ọmọ wọn máa kú, ohun tí Jèhófà fẹ́ fáwa èèyàn ò yí pa dà. (Àìsá. 55:11) Ó ṣì ń wù ú pé káwọn olóòótọ́ èèyàn wà láàyè títí láé. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìlérí Jèhófà tó ti ṣẹ. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa jí àwọn tó ti kú dìde, òun sì máa fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Ìṣe 24:15; Títù 1:​1, 2) Ó dá ọkùnrin olóòótọ́ náà Jóòbù lójú pé ó ń wu Jèhófà gan-an láti jí àwọn tó ti kú dìde. (Jóòbù 14:​14, 15) Wòlíì Dáníẹ́lì náà mọ̀ pé Jèhófà máa jí àwọn tó ti kú dìde, á sì fún wọn láǹfààní láti wà láàyè títí láé. (Sm. 37:29; Dán. 12:​2, 13) Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn Júù náà mọ̀ pé Jèhófà lè mú káwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ rí “ìyè àìnípẹ̀kun.” (Lúùkù 10:25; 18:18) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe yìí, kódà nígbà tí Jésù fúnra ẹ̀ kú, Jèhófà Bàbá rẹ̀ ló jí i dìde.—Mát. 19:29; 22:​31, 32; Lúùkù 18:30; Jòh. 11:25. w22.12 4-5 ¶8-9

Monday, July 22

Jèhófà, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.—Sm. 31:14.

Jèhófà rọ̀ wá pé ká sún mọ́ òun. (Jém. 4:8) Òun ni Ọlọ́run wa àti Bàbá wa, ó sì ń fẹ́ ká jẹ́ Ọ̀rẹ́ òun. Ó máa ń dáhùn àwọn àdúrà wa, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Ó ń lo ètò rẹ̀ láti kọ́ wa ká má bàa kó sínú ewu. Tá a bá fẹ́ sún mọ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà, ká máa ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì máa ronú lórí ohun tá a kà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àá sì mọyì ẹ̀. Àwọn nǹkan yìí máa jẹ́ kó wù wá láti ṣe ohun tó fẹ́, ká sì máa yìn ín lógo. (Ìfi. 4:11) Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa fọkàn tán òun àti ètò tó ń lò láti darí wa. Èṣù máa ń ṣe àwọn nǹkan táá mú ká máa ṣiyèméjì díẹ̀díẹ̀ pé Jèhófà àti ètò ẹ̀ ò ṣeé fọkàn tán. Àmọ́ tá a bá ti mọ àwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n Sátánì, a ò ní kó sí pańpẹ́ ẹ̀. Tí ìgbàgbọ́ tá a ní bá lágbára, tá a sì fọkàn tán Jèhófà pátápátá, a ò ní fi Ọlọ́run àti ètò ẹ̀ sílẹ̀.—Sm. 31:​13, 14. w22.11 14 ¶1-3

Tuesday, July 23

Wọ́n . . . ṣe tán láti kú dípò kí wọ́n sin ọlọ́run míì yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn tàbí kí wọ́n jọ́sìn rẹ̀.—Dán. 3:28.

Ọjọ́ pẹ́ táwọn Kristẹni tòótọ́ ti ń fi ẹ̀mí wọn wewu torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì gbà pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Bíi tàwọn Hébérù mẹ́ta tí wọ́n jù sínú iná ìléru àmọ́ tí Ẹni Tó Lágbára Jù Lọ gbà wọ́n sílẹ̀ torí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́, bẹ́ẹ̀ náà làwa Kristẹni tòótọ́ ṣe pinnu pé Jèhófà la máa jẹ́ olóòótọ́ sí. Dáfídì sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Jèhófà yóò ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn. Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi àti gẹ́gẹ́ bí ìwà títọ́ mi.” (Sm. 7:8) Dáfídì tún sọ pé: “Ìwà títọ́ àti ìdúróṣinṣin máa dáàbò bò mí.” (Sm. 25:21) Torí náà, ohun tó máa jẹ́ ká gbádùn ayé wa ni pé ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ká má fi í sílẹ̀ rárá bá a tiẹ̀ ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro! Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwa náà máa lè sọ bíi ti onísáàmù pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ . . . , tó ń rìn nínú òfin Jèhófà.”—Sm. 119:​1, àlàyé ìsàlẹ̀. w22.10 17 ¶18-19

Wednesday, July 24

Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí . . . látinú àwọn ohun tó dá.—Róòmù 1:20.

Nígbà ayé Jóòbù, onírúurú èèyàn ló bá sọ̀rọ̀. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí òun àti Jèhófà jọ sọ ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an. Nígbà tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀, Jèhófà sọ fún Jóòbù pé kó kíyè sí díẹ̀ lára àwọn nǹkan àgbàyanu tóun dá. Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé ọlọ́gbọ́n ni òun àti pé òun máa ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ òun. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run rán Jóòbù létí pé tóun bá lè bójú tó àwọn ẹranko, òun máa lè bójú tó òun náà. (Jóòbù 38:​39-41; 39:​1, 5, 13-16) Nígbà tí Jóòbù kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, ó kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà, ó sì jẹ́ kó mọ àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní. Táwa náà bá ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, á jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ó lè má rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ ìlú ńlá lò ń gbé, ó lè jẹ́ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà dá lò ń rí lójoojúmọ́. Tó bá sì jẹ́ ìgbèríko lò ń gbé, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò ráyè tó láti kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, àmọ́ ó ṣe pàtàkì pé ká máa wáyè, ká sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. w23.03 15 ¶1-2

Thursday, July 25

Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́.—Òwe 22:3.

Jésù sọ pé “ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára” àtàwọn àjálù míì máa ṣẹlẹ̀ kí òpin tó dé. (Lúùkù 21:11) Ó tún sọ pé “ìwà tí kò bófin mu máa pọ̀ sí i,” àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì ń ṣẹ lónìí torí pé ìwà ọ̀daràn, ìwà ipá àtàwọn afẹ̀míṣòfò túbọ̀ ń pọ̀ sí i. (Mát. 24:12) Jésù ò sọ pé àwọn tí ò ṣèfẹ́ Ọlọ́run nìkan làwọn àjálù yìí á máa ṣẹlẹ̀ sí. Kódà, ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ni àjálù ti ṣẹlẹ̀ sí. (Àìsá. 57:1; 2 Kọ́r. 11:25) Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáàbò bò wá lọ́nà ìyanu tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àmọ́ ó dájú pé ó máa pèsè gbogbo ohun tá a nílò kọ́kàn wa lè balẹ̀, ká sì wà ní àlàáfíà. Tá a bá ti múra sílẹ̀ de àjálù, a ò ní kọ́kàn sókè tí àjálù bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ lójijì. Àmọ́ tá a bá múra sílẹ̀ de àjálù, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa dáàbò bò wá? Rárá o. Kódà, bá a ṣe múra sílẹ̀ de àjálù yẹn gan-an ló fi hàn pé a gbà pé Jèhófà máa bójú tó wa. Lọ́nà wo? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá nímọ̀ràn pé ká máa múra sílẹ̀ de àwọn àjálù tó lè ṣẹlẹ̀. w22.12 18 ¶9-10

Friday, July 26

Ọlọ́run ti rán mi ṣáájú yín láti gba ẹ̀mí là.—Jẹ́n. 45:5.

Nígbà tí Jósẹ́fù wà lẹ́wọ̀n, Jèhófà mú kí Fáráò ọba Íjíbítì lá àlá méjì tó bà á lẹ́rù. Nígbà tó gbọ́ pé Jósẹ́fù lè túmọ̀ àlá, ó ní kí wọ́n lọ mú un wá. Jèhófà ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ láti túmọ̀ àwọn àlá náà. Inú Fáráò sì dùn gan-an nígbà tí Jósẹ́fù gbà á nímọ̀ràn ohun tó máa ṣe. Fáráò rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ló bá fi ṣe alábòójútó oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. (Jẹ́n. 41:​38, 41-44) Nígbà tó yá, ìyàn ńlá kan mú nílẹ̀ Íjíbítì àti láwọn ilẹ̀ míì, kódà ó dé ilẹ̀ Kénáánì níbi táwọn èèyàn Jósẹ́fù ń gbé. Ní báyìí, Jósẹ́fù ti wà nípò tó ti lè gba ìdílé ẹ̀ sílẹ̀, ìyẹn ni ò sì ní jẹ́ kí ìdílé tí Mèsáyà ti máa wá pa run. Ó dájú pé Jèhófà ló wà lẹ́yìn Jósẹ́fù tí gbogbo ohun tó ń ṣe fi yọrí sí rere. Jèhófà yí gbogbo aburú táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣe sí i pa dà, ìyẹn sì wá mú kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ. w23.01 17 ¶11-12

Saturday, July 27

Ẹ máa kíyè sí ara yín.—Lúùkù 21:34.

Ẹni tó ń kíyè sí ara ẹ̀ máa ń ṣọ́ra kí nǹkan kan má bàa ba àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ó sì máa ń yẹra fáwọn nǹkan náà. Tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, àá máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Òwe 22:3; Júùdù 20, 21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni nímọ̀ràn pé ká máa kíyè sára wa. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe bí aláìlọ́gbọ́n àmọ́ bí ọlọ́gbọ́n.” (Éfé. 5:​15, 16) Gbogbo ìgbà ni Sátánì máa ń gbìyànjú láti ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá nímọ̀ràn pé ká “máa fi òye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́” ká lè borí gbogbo àdánwò Sátánì. (Éfé. 5:17) Torí náà, tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu tó tọ́, a gbọ́dọ̀ fòye mọ ohun tí “ìfẹ́ Jèhófà” jẹ́. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, tá a sì ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà. Bá a bá ṣe ń mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́, tá a sì ń sapá láti ní “èrò inú Kristi,” àá túbọ̀ máa hùwà “bí ọlọ́gbọ́n,” kódà tí Bíbélì ò bá sọ ohun tó yẹ ká ṣe nírú ipò bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́r. 2:​14-16. w23.02 16-17 ¶7-9

Sunday, July 28

Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà, kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.—Róòmù 12:2.

Ṣé o máa ń tọ́jú ilé ẹ déédéé? Bóyá kó o tó kó sínú ilé náà, ṣe lo fara balẹ̀ tún un ṣe. Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ tó ò bá tọ́jú ẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tó o kó sínú ẹ̀? Eruku àti ìdọ̀tí máa kún inú ilé náà. Torí náà, tó o bá fẹ́ kí ilé ẹ dùn ún wò, ó yẹ kó o máa tún un ṣe déédéé. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká ṣiṣẹ́ kára ká lè yí èrò àti ìwà wa pa dà. Ó dájú pé ká tó ṣèrìbọmi, a ti ṣiṣẹ́ kára láti ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé wa, ká lè “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́r. 7:1) Àmọ́ ní báyìí, ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé “ẹ máa di tuntun.” (Éfé. 4:23) Torí pé ìwà àti ìṣe ayé yìí tó dà bí eruku àti ìdọ̀tí lè sọ wá di aláìmọ́ lójú Jèhófà. Kíyẹn má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa, kí Jèhófà sì lè tẹ́wọ́ gbà wá, ó yẹ ká máa yẹ ara wa wò déédéé, ìyẹn èrò wa, ìwà wa àti ohun tó ń wù wá. w23.01 8 ¶1-2

Monday, July 29

Ó rí i tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀.—Mát. 3:16.

Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ ká sọ pé o wà níbi tí Jésù ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? Ó dájú pé inú ẹ máa dùn gan-an bí Jésù ṣe ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ láìwo ìwé rárá! Ìgbà tí Jésù ṣèrìbọmi, tí Jèhófà sì fẹ̀mí mímọ́ yàn án ni Jèhófà jẹ́ kó rántí àwọn nǹkan tó ti kọ́ lọ́run kó tó wá sáyé. Kódà, inú Ìwé Mímọ́ ni Jésù ti fa ọ̀rọ̀ tó sọ yọ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi àtàwọn ọ̀rọ̀ tó sọ kẹ́yìn kó tó kú. (Diu. 8:3; Sm. 31:5; Lúùkù 4:4; 23:46) Yàtọ̀ síyẹn, ní gbogbo ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó fi wàásù nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ka Ìwé Mímọ́, tó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹ̀, tó sì ṣàlàyé ẹ̀ ní gbangba. (Mát. 5:​17, 18, 21, 22, 27, 28; Lúùkù 4:​16-20) Ọ̀pọ̀ ọdún kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ló ti máa ń ka Ìwé Mímọ́, tó sì máa ń gbọ́ báwọn míì ṣe ń kà á. Ó dájú pé á máa gbọ́ bí Màríà àti Jósẹ́fù ṣe ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nínú ilé. (Diu. 6:​6, 7) Gbogbo ọjọ́ Sábáàtì ni Jésù àti ìdílé ẹ̀ máa ń lọ sínú sínágọ́gù. (Lúùkù 4:16) Kò sí àní-àní pé Jésù máa ń tẹ́tí sílẹ̀ gan-an bí wọ́n ṣe ń ka Ìwé Mímọ́ tí wọ́n bá débẹ̀. w23.02 8 ¶1-2

Tuesday, July 30

Kí o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.—Máàkù 12:30.

Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, o ti wá mọ̀ pé Jèhófà ni “orísun ìyè” àti pé òun ló fún wa ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Sm. 36:9; Jém. 1:17) Torí náà, Ọlọ́run ló fún ẹ ní gbogbo ohun rere tó ò ń gbádùn torí pé ọ̀làwọ́ ni, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa. Ìràpadà ni ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa, ó sì ṣeyebíye. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn tó. Jésù sọ pé: ‘Baba nífẹ̀ẹ́ mi,’ ‘mo sì nífẹ̀ẹ́ Baba.’ (Jòh. 10:17; 14:31) Àtìgbà tí wọ́n ti jọ wà pa pọ̀ fún àìmọye ọdún ni ìfẹ́ tó wà láàárín wọn ti ń lágbára sí i. (Òwe 8:​22, 23, 30) Ẹ wo bó ṣe máa dun Ọlọ́run tó nígbà tó gbà kí wọ́n fìyà jẹ Ọmọ ẹ̀, tó sì kú. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ aráyé títí kan ìwọ náà. Ìdí nìyẹn tó ṣe fi Ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ, kí ìwọ àtàwọn ẹlòmíì lè wà láàyè títí láé. (Jòh. 3:16; Gál. 2:20) Kò sí ìdí míì tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. w23.03 4-5 ¶11-13

Wednesday, July 31

Ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin.—Ìfi. 2:25.

A gbọ́dọ̀ ta ko ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà. Jésù bá àwọn kan ní Págámù wí torí pé wọ́n ń fa ìyapa nínú ìjọ. (Ìfi. 2:​14-16) Ó gbóríyìn fún àwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà torí wọ́n ti yẹra fún “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì,” ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ‘di òtítọ́ mú ṣinṣin.’ (Ìfi. 2:​24-26) Torí náà, ó yẹ káwọn Kristẹni tó ti gba ẹ̀kọ́ èké ronú pìwà dà. Kí làwa náà gbọ́dọ̀ ṣe lónìí? A gbọ́dọ̀ ta ko ẹ̀kọ́ èyíkéyìí tó lòdì sí èrò Jèhófà. Àwọn apẹ̀yìndà lè “jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn,” àmọ́ ‘ìṣe wọn ò fi agbára Ọlọ́run hàn.’ (2 Tím. 3:5) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, ó máa rọrùn fún wa láti mọ ẹ̀kọ́ èké, ká sì ta kò ó. (2 Tím. 3:​14-17; Júùdù 3, 4) A gbọ́dọ̀ jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Tá a bá ti ń ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, ó yẹ ká ṣàtúnṣe ká lè rí ojúure ẹ̀.—Ìfi. 2:​5, 16; 3:​3, 16. w22.05 4 ¶9; 5 ¶11

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́