ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es24 ojú ìwé 88-98
  • September

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • September
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Sunday, September 1
  • Monday, September 2
  • Tuesday, September 3
  • Wednesday, September 4
  • Thursday, September 5
  • Friday, September 6
  • Saturday, September 7
  • Sunday, September 8
  • Monday, September 9
  • Tuesday, September 10
  • Wednesday, September 11
  • Thursday, September 12
  • Friday, September 13
  • Saturday, September 14
  • Sunday, September 15
  • Monday, September 16
  • Tuesday, September 17
  • Wednesday, September 18
  • Thursday, September 19
  • Friday, September 20
  • Saturday, September 21
  • Sunday, September 22
  • Monday, September 23
  • Tuesday, September 24
  • Wednesday, September 25
  • Thursday, September 26
  • Friday, September 27
  • Saturday, September 28
  • Sunday, September 29
  • Monday, September 30
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
es24 ojú ìwé 88-98

September

Sunday, September 1

Tí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń jọ́sìn Ọlọ́run, àmọ́ tí kò ṣọ́ ahọ́n rẹ̀ gidigidi, ṣe ló ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, asán sì ni ìjọsìn rẹ̀.—Jém. 1:26.

Tá a bá ń lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ wa lọ́nà tó dáa, ìyẹn máa fi hàn pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá. A tún máa jẹ́ kí àwọn èèyàn tá a jọ wà ládùúgbò rí ìyàtọ̀ tó wà “láàárín ẹni tó ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” (Mál. 3:18) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Kimberly nìyẹn. Wọ́n ní kí òun àti ọmọ kíláàsì ẹ̀ kan jọ ṣiṣẹ́ kan pa pọ̀ nílé ìwé. Lẹ́yìn tí wọ́n parí iṣẹ́ náà, ọmọ kíláàsì ẹ̀ yẹn kíyè sí i pé Kimberly yàtọ̀ sáwọn ọmọ kíláàsì tó kù. Ó rí i pé Kimberly kì í sọ̀rọ̀ àwọn míì láìdáa, ara ẹ̀ yá mọ́ọ̀yàn, kì í sì í sọ̀sọkúsọ. Ohun tí Kimberly ṣe yìí wú ọmọ kíláàsì ẹ̀ lórí gan-an débi pé ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà máa ń dùn gan-an tó bá rí i pé à ń lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ wa lọ́nà tó dáa débi pé àwọn èèyàn wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́! Gbogbo wa la máa ń fẹ́ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa fògo fún Jèhófà, tó sì máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará wa. w22.04 5-6 ¶5-7

Monday, September 2

Àwọn obìnrin . . . ń fi àwọn ohun ìní wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.—Lúùkù 8:3.

Jésù gba Màríà Magidalénì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù méje tó ń yọ ọ́ lẹ́nu. Torí pé ó mọyì ohun tí Jésù ṣe fún un, ó di ọmọlẹ́yìn ẹ̀, ó sì ń ran Jésù lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Lúùkù 8:​1-3) Òótọ́ ni pé Màríà mọyì ohun tí Jésù ṣe fún un gan-an, síbẹ̀ ó ṣeé ṣe kó má mọ̀ pé Jésù ṣì máa ṣe ohun tó dáa jùyẹn lọ fóun. Ìyẹn ni pé ó máa fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ “kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀” lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 3:16) Síbẹ̀, Màríà ṣe ohun tó fi hàn pé ó mọyì ohun tí Jésù ṣe fún un. Nígbà tí Jésù ń jìyà lórí òpó igi oró, Màríà dúró tì í, ó sì ń tu Jésù àtàwọn tí wọ́n jọ wà níbẹ̀ nínú. (Jòh. 19:25) Lẹ́yìn tí Jésù kú, Màríà àtàwọn obìnrin méjì míì gbé àwọn èròjà tó ń ta sánsán wá kí wọ́n lè fi pa òkú Jésù lára. (Máàkù 16:​1, 2) Màríà láǹfààní láti rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde, ó sì tún bá a sọ̀rọ̀. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni ò nírú àǹfààní yẹn.—Jòh. 20:​11-18. w23.01 27 ¶4

Tuesday, September 3

Ì bá wù mí kí o tutù tàbí kí o gbóná.—Ìfi. 3:15.

Kò yẹ ká máa rò pé ohun tá a ti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ti tó, ká wá sọ pé kò yẹ ká ṣe sí i mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè má rọrùn fún wa láti ṣe tó ohun tá à ń ṣe tẹ́lẹ̀, ó yẹ ká tẹra mọ́ “iṣẹ́ Olúwa,” ká sì máa kíyè sára títí òpin á fi dé. (1 Kọ́r. 15:58; Mát. 24:13; Máàkù 13:33) A gbọ́dọ̀ nítara, ká sì máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. Ìṣòro míì ni Jésù mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ fún àwọn ará Laodíkíà. Wọ́n “lọ́wọ́ọ́wọ́” nínú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run. Torí pé wọn ò fi ìtara jọ́sìn Jèhófà, Jésù sọ fún wọn pé “akúṣẹ̀ẹ́” àti “ẹni téèyàn ń káàánú” ni wọ́n. Ó yẹ kí wọ́n máa fi ìtara jọ́sìn Jèhófà. (Ìfi. 3:​16, 17, 19) Kí la rí kọ́? Tá ò bá fi bẹ́ẹ̀ nítara mọ́, ṣe ló yẹ ká túbọ̀ máa mọrírì gbogbo ohun tí Jèhófà àti ètò rẹ̀ ń ṣe fún wa. (Ìfi. 3:18) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí nǹkan tara gbà wá lọ́kàn débi tá ò fi ní ráyè fún ìjọsìn Jèhófà mọ́. w22.05 3-4 ¶7-8

Wednesday, September 4

Wọ́n sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀ torí àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà.—Mál. 3:16.

Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń kọ ìwé kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Orúkọ àwọn èèyàn ló wà nínú ìwé náà, Ébẹ́lì sì ni ẹlẹ́rìí olóòótọ́ àkọ́kọ́ tí Jèhófà kọ orúkọ ẹ̀ sínú ẹ̀. (Lúùkù 11:​50, 51) Látìgbà yẹn títí di báyìí, Jèhófà ti kọ orúkọ ọ̀pọ̀ àwọn míì sínú ìwé yẹn. Nínú Bíbélì, àwọn orúkọ tá a pe ìwé náà ni “ìwé ìrántí,” “ìwé ìyè” àti “àkájọ ìwé ìyè.” (Mál. 3:16; Ìfi. 3:5; 17:8) Orúkọ àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà, tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ la kọ sínú ìwé tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. Wọ́n máa láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Lónìí, tá a bá fẹ́ kí Jèhófà kọ orúkọ wa sínú ìwé náà, àfi ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ẹ̀, ẹbọ ìràpadà Ọmọ ẹ̀ Jésù Kristi ló sì máa jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe. (Jòh. 3:​16, 36) Gbogbo wa la fẹ́ kí orúkọ wa wà nínú ìwé ìyè, bóyá ọ̀run la máa gbé tàbí ayé. w22.09 14 ¶1-2

Thursday, September 5

A . . . ju Èṣù tó ń ṣì wọ́n lọ́nà sínú adágún iná àti imí ọjọ́.—Ìfi. 20:10.

Ìwé Ìfihàn sọ̀rọ̀ nípa “dírágónì ńlá aláwọ̀ iná” kan. (Ìfi. 12:3) Dírágónì yìí bá Jésù àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jà. (Ìfi. 12:​7-9) Ó gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì ń fún àwọn ẹranko ẹhànnà náà lágbára. (Ìfi. 12:17; 13:4) Ta ni dírágónì náà? Òun ni “ejò àtijọ́ náà, ẹni tí à ń pè ní Èṣù àti Sátánì.” (Ìfi. 12:9; 20:2) Òun ló ń ti gbogbo àwọn ọ̀tá Jèhófà lẹ́yìn. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí dírágónì náà? Ìfihàn 20:​1-3 sọ pé áńgẹ́lì kan máa sọ Sátánì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, tó dà bí ọgbà ẹ̀wọ̀n. Nígbà tí Sátánì bá wà lẹ́wọ̀n, kò ní “ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà fi máa parí.” Níkẹyìn, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù máa pa run títí láé torí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa jù wọ́n “sínú adágún iná àti imí ọjọ́.” Ẹ fojú inú wo bí ayé ṣe máa rí nígbà tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ò bá sí mọ́. Ayé yìí á mà dáa gan-an o! w22.05 14 ¶19-20

Friday, September 6

Kó máa ṣiṣẹ́ kára, kó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere, kó lè ní nǹkan tó máa fún ẹni tí kò ní.—Éfé. 4:28.

Òṣìṣẹ́ kára ni Jésù. Nígbà tí Jésù wà lọ́dọ̀ọ́, iṣẹ́ káfíńtà ló ṣe. (Máàkù 6:3) Ó dájú pé àwọn òbí ẹ̀ mọyì ìrànlọ́wọ́ tó ṣe fún wọn kí wọ́n lè pèsè ohun tí ìdílé wọn nílò. Torí pé ẹni pípé ni Jésù, àwọn èèyàn máa fẹ́ràn iṣẹ́ tó bá ṣe gan-an! Ó sì dájú pé Jésù náà gbádùn iṣẹ́ yẹn gan-an. Síbẹ̀, bí Jésù ṣe ń ṣiṣẹ́ káfíńtà ẹ̀ lọ, ó ṣì ya àkókò sọ́tọ̀ láti fi ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. (Jòh. 7:15) Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sọ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pé: “Ẹ má ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó ń ṣègbé, àmọ́ ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó wà fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 6:27) Bákan náà, nínú Ìwàásù orí Òkè, Jésù sọ pé: “Ẹ to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run.” (Mát. 6:20) Tá a bá ń lo ọgbọ́n Ọlọ́run, ó máa ń jẹ́ ká fojú tó tọ́ wo iṣẹ́ oúnjẹ ọ̀ọ̀jọ́ wa. A ti kọ́ àwa Kristẹni pé ká “máa ṣiṣẹ́ kára . . . , iṣẹ́ rere.” w22.05 22 ¶9-10

Saturday, September 7

Ìyá rẹ yóò máa yọ̀.—Òwe 23:25.

Yùníìsì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún Tímótì. Ó dájú pé á ti rí i nínú ìwà ìyá ẹ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Ó sì tún rí i pé inú ìyá òun ń dùn bó ṣe ń sin Jèhófà. Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ ìyá lónìí ti ran àwọn ìdílé wọn lọ́wọ́ “láìsọ ohunkóhun.” (1 Pét. 3:​1, 2) Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Báwo lo ṣe máa ṣe é? Fi àjọṣe ìwọ àti Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́. (Diu. 6:​5, 6) Bíi ti ọ̀pọ̀ ìyá, ìwọ náà ti gbé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe. O ti lo àkókò ẹ, owó àtàwọn nǹkan míì láti fi tọ́jú àwọn ọmọ ẹ. Ìgbà míì sì rèé, o ò kì í sùn kó o lè bójú tó wọn. Àmọ́ má jẹ́ kí ọwọ́ ẹ dí jù débi pé o ò ní ráyè ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ lágbára. Máa ya àkókò sọ́tọ̀ tí wàá fi máa dá gbàdúrà àtèyí tí wàá fi máa dá kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì máa lọ sípàdé déédéé. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àjọṣe ìwọ àti Jèhófà á túbọ̀ lágbára, wàá sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún ìdílé ẹ àtàwọn ẹlòmíì. w22.04 16 ¶1; 19 ¶12-13

Sunday, September 8

Kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kí o pe ẹni burúkú ní ẹlẹ́bi, kí o sì jẹ́ kí ohun tó ṣe dà lé e lórí, kí o pe olódodo ní aláìṣẹ̀, kí o sì san èrè . . . fún un.—1 Ọba 8:32.

Inú wa dùn pé kì í ṣe àwa ni Jèhófà ní ká máa pinnu ìdájọ́ tẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa gbà! Jèhófà tó jẹ́ Onídàájọ́ Tó Ga Jù Lọ ló máa ṣiṣẹ́ pàtàkì yìí. (Róòmù 14:​10-12) Ó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ṣèdájọ́ òdodo, ó sì máa dájọ́ lọ́nà tó tọ́. (Jẹ́n. 18:25) Òdodo ni Jèhófà máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà! À ń retí ìgbà tí Jèhófà máa ṣàtúnṣe gbogbo aburú tí àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ àwa èèyàn ti fà. Tó bá dìgbà yẹn, gbogbo àìlera àti ẹ̀dùn ọkàn ni Jèhófà máa mú kúrò. (Sm. 72:​12-14; Ìfi. 21:​3, 4) A ò ní rántí wọn mọ́ títí láé. Àmọ́ bá a ṣe ń dúró de ìgbà yẹn, inú wa dùn pé Jèhófà ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa dárí jini bíi tiẹ̀. w22.06 13 ¶18-19

Monday, September 9

Ṣé Onídàájọ́ gbogbo ayé kò ní ṣe ohun tó tọ́ ni?—Jẹ́n. 18:25.

Adájọ́ tó dáa máa ń mọ òfin dáadáa. Ó tún gbọ́dọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó dáa àtohun tí ò dáa. Kí ni nǹkan míì tó yẹ kí adájọ́ ṣe? Ó yẹ kó ṣàyẹ̀wò gbogbo ohun tó yẹ kó mọ̀ nípa ẹjọ́ kan kó tó dá ẹjọ́ náà. Torí náà, Jèhófà ni Adájọ́ tó dáa jù torí gbogbo ohun tó yẹ kó mọ̀ ló mọ̀. Jèhófà yàtọ̀ sáwọn adájọ́ tó jẹ́ èèyàn torí gbogbo ohun tó yẹ kó mọ̀ nípa ẹjọ́ kan ló máa ń mọ̀. (Jẹ́n. 18:​20, 21; Sm. 90:8) Kì í ṣe ohun táwọn èèyàn bá rí tàbí ohun tí wọ́n bá sọ ló máa ń fi dájọ́. Ó mọ ohun tó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó mọ bí òun ṣe ṣẹ̀dá wa, irú ilé tá a ti wá, ibi tá a dàgbà sí, bí nǹkan ṣe ń rí lára wa àti ìlera wa. Jèhófà tún máa ń mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Ó mọ ìdí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fi ń ṣe ohun tá à ń ṣe. Kò sí ohun tó pa mọ́ lójú Jèhófà. (Héb. 4:13) Torí náà, tí Jèhófà bá dárí ji ẹnì kan, ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀. w22.06 4 ¶8-9

Tuesday, September 10

Gbogbo ohun tí èèyàn bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀.—Jóòbù 2:4.

Ó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì lò fún Jóòbù torí irú àwọn ọgbọ́n yẹn náà ló ń lò fún wa lónìí. Ohun tí Sátánì ń sọ ni pé a ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti pé tá a bá kojú ìṣòro tó lè gbẹ̀mí wa, a ò ní sin Jèhófà mọ́. Sátánì tún sọ pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé gbogbo nǹkan tá a bá ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀ ò já mọ́ nǹkan kan lójú ẹ̀. Àmọ́ ní báyìí táwa ìránṣẹ́ Jèhófà ti mọ àwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí Sátánì ń lò, a ò ní jẹ́ kó fi mú wa. Tá a bá dojú kọ àwọn àdánwò kan, ó yẹ ká lo àkókò yẹn láti túbọ̀ mọ irú ẹni tá a jẹ́. Àwọn àdánwò tí Jóòbù dojú kọ jẹ́ kó rí àwọn ibi tó kù sí, ó sì ṣàtúnṣe tó yẹ. Ọ̀kan lára àwọn ohun tó kọ́ ni pé ó yẹ kóun túbọ̀ nírẹ̀lẹ̀. (Jóòbù 42:3) Àwa náà lè rí àwọn ibi tá a kù sí tá a bá ń dojú kọ àdánwò. Tá a bá ti rí ibi tá a kù sí, á rọrùn láti ṣàtúnṣe. w22.06 23 ¶13-14

Wednesday, September 11

“Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Jèhófà wí, “Àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn.”—Àìsá. 43:10.

Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, kí Jèhófà tó sọ pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ó ti kọ́kọ́ sọ pé: “Tí o bá gba inú omi kọjá, màá wà pẹ̀lú rẹ, tí o bá sì gba inú odò kọjá, kò ní kún bò ọ́. Tí o bá rin inú iná kọjá, kò ní jó ọ, ọwọ́ iná ò sì ní rà ọ́.” (Àìsá. 43:2) Bí àwa náà ṣe ń wàásù lónìí, a máa ń dojú kọ àwọn ìṣòro tó dà bí odò àti iná. Síbẹ̀, Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa wàásù nìṣó. (Àìsá. 41:13) Ọ̀pọ̀ ni ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù lákòókò tiwa yìí náà. Àmọ́ ó yẹ ká máa rántí pé bí wọn ò tiẹ̀ gbọ́ wa, kò túmọ̀ sí pé a ò ṣàṣeyọrí. A mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa bá ò ṣe jẹ́ kó sú wa, ìyẹn sì ń fún wa lókun láti máa wàásù nìṣó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan máa gba èrè iṣẹ́ tirẹ̀.”—1 Kọ́r. 3:8; 4:​1, 2. w22.11 4 ¶5-6

Thursday, September 12

Ẹ jẹ́ oníwà rere láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.—1 Pét. 2:12.

Lónìí, à ń rí i bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń ṣẹ. Àwọn èèyàn “láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” ń kọ́ bí wọ́n á ṣe máa sọ “èdè mímọ́” tó jẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì. (Sek. 8:23; Sef. 3:9) Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ní orílẹ̀-èdè igba ó lé ogójì (240), iye àwọn tó wà nínú ètò Ọlọ́run ju mílíọ̀nù mẹ́jọ (8,000,000) lọ, àwọn tó ju ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) èèyàn ló sì ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún! Kì í ṣe bí iye wa ṣe pọ̀ tó ló ṣe pàtàkì, àmọ́ bí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni ṣe ń fi “ìwà tuntun” wọ ara wọn láṣọ ló ṣe pàtàkì jù. (Kól. 3:​8-10) Ọ̀pọ̀ lára wọn ló jáwọ́ nínú ìṣekúṣe, ìwà ipá, ìkórìíra àti èrò pé orílẹ̀-èdè tèmi lọ̀gá. Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Àìsáyà 2:4 ti ń ṣẹ, ó sọ pé, ‘wọn ò ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.’ Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ kára, tá à ń gbé ìwà tuntun wọ̀, ìyẹn ń mú káwọn èèyàn máa wá sínú ètò Ọlọ́run, àwa náà sì ń fi hàn pé à ń tẹ̀ lé Jésù Kristi tó ń darí wa. (Jòh. 13:35) Àwọn nǹkan yìí ò ṣèèṣì ṣẹlẹ̀ o, ìdí ni pé Jésù ló ń ràn wá lọ́wọ́. w22.07 9 ¶7-8

Friday, September 13

Kí àdúrà mi dà bíi tùràrí tí a ṣètò sílẹ̀ níwájú rẹ.—Sm. 141:2.

Tá a bá ń gbàdúrà, kò yẹ ká máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ bíi pé ẹgbẹ́ ni wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká bá a sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ẹ jẹ́ ká ronú lórí ìran àgbàyanu tí Àìsáyà, Ìsíkíẹ́lì, Dáníẹ́lì àti Jòhánù rí. Gbogbo wọn ló jẹ́ ká mọ̀ pé Ọba alágbára ńlá ni Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Àìsáyà “rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ gíga, tó sì ta yọ.” (Àìsá. 6:​1-3) Ìsíkíẹ́lì rí Jèhófà tó jókòó sórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin, tí ‘ìmọ́lẹ̀ tó tàn yòò bí òṣùmàrè sì yí i ká.’ (Ìsík. 1:​26-28) Dáníẹ́lì rí “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé” tó wọ aṣọ funfun, iná sì ń jáde láti inú ìtẹ́ Rẹ̀. (Dán. 7:​9, 10) Jòhánù náà rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́, òṣùmàrè kan tó dà bí òkúta émírádì sì yí ìtẹ́ náà ká. (Ìfi. 4:​2-4) Torí náà, bá a ṣe ń ronú lórí bí ọlá ńlá Jèhófà ṣe tóbi tó, ó yẹ ká máa rántí pé àǹfààní ńlá la ní láti gbàdúrà sí i, ó sì yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. w22.07 20 ¶3

Saturday, September 14

[Ẹ ṣọ́ra] fún ẹ̀tàn àwọn èèyàn.—Éfé. 4:14.

Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, mọ̀ dájú pé Sátánì á máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà má bàa lágbára mọ́. Ọ̀nà kan tí Sátánì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó jẹ́ kó o máa ṣiyèméjì nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè fẹ́ kó o gbà pé Ọlọ́run kọ́ ló dá wa àti pé àwọn nǹkan tó wà láyé yìí kàn ṣàdédé wà ni. O lè má nírú èrò yẹn nígbà tó o wà lọ́mọdé, àmọ́ ní báyìí tó o ti dàgbà, wọ́n á fẹ́ fi ẹ̀kọ́ yìí kọ́ ẹ nílé ìwé. Àlàyé tí olùkọ́ ẹ máa ṣe nípa ẹ̀kọ́ yìí lè fẹ́ bọ́gbọ́n mu lóòótọ́, ó sì lè mú kó o fẹ́ gba ẹ̀kọ́ náà gbọ́. Àmọ́, àwọn olùkọ́ ẹ lè má tíì gbé ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà yẹ̀ wò. Rántí ìlànà tó wà ní Òwe 18:17 tó sọ pé: “Ẹni tó bá kọ́kọ́ ro ẹjọ́ rẹ̀ ló ń dà bíi pé ó jàre, títí ẹnì kejì fi wá, tó sì bi í ní ìbéèrè.” Dípò tí wàá kàn gba ohun tí wọ́n sọ fún ẹ nílé ìwé gbọ́, ńṣe ló yẹ kó o fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtohun tí ìwé ètò Ọlọ́run sọ kó o lè mọ òótọ́. w22.08 2 ¶2; 4 ¶8

Sunday, September 15

Kí o rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀; ìgbà yẹn ni ọ̀nà rẹ máa yọrí sí rere, tí wàá sì máa hùwà ọgbọ́n.—Jóṣ. 1:8.

Ó yẹ ká lóye ohun tá à ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a ò ní jàǹfààní kankan nínú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jésù sọ nígbà tó ń bá “ọkùnrin kan tó mọ Òfin dunjú” sọ̀rọ̀. (Lúùkù 10:​25-29) Nígbà tí ọkùnrin yẹn béèrè pé kí lòun máa ṣe kóun lè ní ìyè àìnípẹ̀kun, Jésù darí ẹ̀ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì bi í pé: “Kí la kọ sínú Òfin? Kí lo kà níbẹ̀?” Ọkùnrin yẹn dáhùn ìbéèrè Jésù dáadáa, ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹsẹ Bíbélì tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa. (Léf. 19:18; Diu. 6:5) Àmọ́ ẹ kíyè sí ìbéèrè tí ọkùnrin yẹn bi Jésù lẹ́yìn ìyẹn, ó ní: “Ta ni ọmọnìkejì mi gan-an?” Ohun tí ọkùnrin yẹn ń sọ ni pé òun ò lóye ohun tí òun kà. Torí náà, kò mọ bó ṣe máa lo ohun tó kà nínú Ìwé Mímọ́ nígbèésí ayé ẹ̀. Ká tó lè lóye ohun tá à ń kà nínú Bíbélì, àfi ká bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ká lè pọkàn pọ̀, ká sì ní kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè fi ohun tá à ń kọ́ sílò. w23.02 9 ¶4-5

Monday, September 16

Ẹ máa rìn nínú òtítọ́.—3 Jòh. 4.

“Báwo lo ṣe rí òtítọ́?” Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn ti bi ẹ́ ní ìbéèrè yìí tó o sì dá wọn lóhùn. Ọ̀kan lára ìbéèrè tá a máa ń kọ́kọ́ bi àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà nìyẹn tá a bá fẹ́ túbọ̀ mọ̀ wọ́n. Ó máa ń wù wá ká mọ bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ṣe mọ Jèhófà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì tún máa ń wù wá láti sọ ìdí tá a fi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún wọn. (Róòmù 1:11) Bá a ṣe ń bá ara wa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí, ó máa ń jẹ́ ká ronú nípa ohun tó mú ká di ìránṣẹ́ Jèhófà. Á tún jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé àá máa “rìn nínú òtítọ́,” ìyẹn ni pé àá máa gbé ìgbé ayé tí inú Jèhófà dùn sí. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú ká nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú wọn ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́. Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló lágbára jù lọ, òun ló sì dá ayé àtọ̀run. Yàtọ̀ síyẹn, òun ni Bàbá wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì ń bójú tó wa.—1 Pét. 5:7. w22.08 14 ¶1, 3

Tuesday, September 17

Fi àwọn aláìní sọ́kàn.—Gál. 2:10.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará pé kí wọ́n máa ṣe “iṣẹ́ rere” kí wọ́n lè fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará. (Héb. 10:24) Yàtọ̀ sí pé Pọ́ọ̀lù máa ń sọ ohun tó ń gbé àwọn ará ró, ó tún máa ń ṣoore fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí ìyàn mú àwọn ará ní Jùdíà, Pọ́ọ̀lù wà lára àwọn tó lọ pín nǹkan fún wọn. (Ìṣe 11:​27-30) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni ni Pọ́ọ̀lù gbájú mọ́, ó tún máa ń fún àwọn èèyàn lóhun tí wọ́n nílò. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe yìí jẹ́ káwọn ará gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa bójú tó àwọn. Bákan náà lónìí, tá a bá ń lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ẹ̀bùn wa láti ran àwọn ará tí àjálù dé bá lọ́wọ́, àwa náà ń gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará wa ró nìyẹn. A tún ń gbé ìgbàgbọ́ wọn ró tá a bá ń fowó ṣètìlẹyìn déédéé fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí àtàwọn nǹkan míì, ó máa jẹ́ káwọn ará wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé kò ní fi wọ́n sílẹ̀. w22.08 24 ¶14

Wednesday, September 18

A ò fìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípasẹ̀ ìfẹ́ èèyàn, àmọ́ àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.—2 Pét. 1:21.

Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ ló wà nínú Bíbélì, kódà ọ̀pọ̀ ọdún káwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ṣẹ ni wọ́n ti kọ wọ́n sílẹ̀. Ìtàn sì fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ. Èyí ò yà wá lẹ́nu torí a mọ̀ pé Jèhófà ló sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun ìlú Bábílónì àtijọ́. Ní nǹkan bí ọdún 778 sí 732 Ṣ.S.K., Jèhófà mí sí wòlíì Àìsáyà láti sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣẹ́gun ìlú Bábílónì. Kódà, ó sọ pé Kírúsì ló máa ṣẹ́gun ìlú náà, ó sì sọ bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun ẹ̀. (Àìsá. 44:27–45:2) Àìsáyà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa pa ìlú náà run pátápátá, kò sì sẹ́ni táá máa gbébẹ̀ mọ́ láé. (Àìsá. 13:​19, 20) Níkẹyìn, àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun ìlú Bábílónì lọ́dún 539 Ṣ.S.K., ìlú alágbára yìí sì ti pa run pátápátá báyìí. w23.01 4 ¶10

Thursday, September 19

Ẹ máa fún ara yín níṣìírí.—1 Tẹs. 5:11.

Jèhófà ti yàn wá pé ká wà lára àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀ kárí ayé lónìí. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn, ọ̀pọ̀ ohun rere la sì ń gbádùn torí pé à ń jọ́sìn Jèhófà! (Máàkù 10:​29, 30) Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bíi tiwa wà kárí ayé, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀. Èdè wa, àṣà ìbílẹ̀ wa àti bá a ṣe ń múra lè yàtọ̀ sí tiwọn, síbẹ̀ a máa ń fìfẹ́ hàn sí wọn tó bá tiẹ̀ jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tá a máa rí wọn nìyẹn. Inú wa máa ń dùn láti wà pẹ̀lú wọn ká lè jọ máa yin Jèhófà Bàbá wa ọ̀run, ká sì máa jọ́sìn ẹ̀ níṣọ̀kan. Àsìkò yìí gan-an ló ṣe pàtàkì jù pé ká wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará wa. (Sm. 133:1) Ìdí ni pé nígbà míì, àwọn ló máa ń bá wa gbé àwọn ìṣòro tó dà bí ẹrù tó wúwo. (Róòmù 15:1; Gál. 6:2) Wọ́n tún máa ń gbà wá níyànjú pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, wọ́n sì ń jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára. (Héb. 10:​23-25) Ẹ wo bí nǹkan ì bá ṣe rí fún wa ká sọ pé a ò ní àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti dúró sọ́dọ̀ Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sátánì àti ayé burúkú yìí ń gbógun tì wá. w22.09 2-3 ¶3-4

Friday, September 20

Ẹni tó bá ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀ á máa fi ọgbọ́n hùwà.—Òwe 10:19.

Ó lè ṣòro fún wa láti kó ara wa níjàánu nígbà tá a bá ń lo ìkànnì àjọlò. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè sọ̀rọ̀ àṣírí kan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lórí ìkànnì láì mọ̀ọ́mọ̀. Táwọn èèyàn bá sì ti mọ ọ̀rọ̀ àṣírí náà, a ò mọ ohun tí wọ́n lè fi ṣe àti jàǹbá tó lè fà. Bákan náà, táwọn alátakò bá ń dọ́gbọ́n tó máa mú ká sọ̀rọ̀ àṣírí tó máa ṣàkóbá fáwọn ará, ó yẹ ká kó ara wa níjàánu, ká má sì sọ nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ táwọn ọlọ́pàá bá ń fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa tàbí tí wọ́n ti ń dí iṣẹ́ wa lọ́wọ́. Tá a bá bá ara wa nírú ipò yìí àti láwọn ipò míì, a lè lo ìlànà Bíbélì tó sọ pé ká “fi ìbonu bo ẹnu” wa. (Sm. 39:1) Ó yẹ ká máa ṣe ohun táá jẹ́ kí gbogbo èèyàn fọkàn tán wa, títí kan àwọn ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tàbí àwọn ẹlòmíì. Torí náà, tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa, a gbọ́dọ̀ máa kó ara wa níjàánu. w22.09 13 ¶16

Saturday, September 21

Aláyọ̀ ni ẹni tí . . . òfin Jèhófà máa ń mú inú rẹ̀ dùn, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru.—Sm. 1:​1, 2.

Tá a bá fẹ́ láyọ̀ tòótọ́, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Ohun tó sì yẹ ká máa ṣe nìyẹn. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.” (Mát. 4:4) Torí náà, kò yẹ ká jẹ́ kí ọjọ́ kan kọjá láì ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó ti sọ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ ká láyọ̀ fún wa nínú Bíbélì. Ó sọ ìdí tó fi dá wa. Ó tún sọ bá a ṣe lè sún mọ́ òun àti bá a ṣe lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà. Kódà, ó jẹ́ ká mọ àwọn ohun rere tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. (Jer. 29:11) Àwọn nǹkan tí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ yìí ń fún wa láyọ̀, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa! Bíbélì tún fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó dáa tá a lè máa tẹ̀ lé nígbèésí ayé wa. Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn yẹn, a máa láyọ̀. Ìgbàkigbà tí ìṣòro bá ń kó ẹ lọ́kàn sókè, ṣe ni kó o tẹra mọ́ Bíbélì kíkà, kó o sì máa ronú lórí ohun tó o kà. w22.10 7 ¶4-6

Sunday, September 22

Ẹ dàgbà di géńdé nínú òye.—1 Kọ́r. 14:20.

Ó nídìí tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé ká má ṣe jẹ́ aláìmọ̀kan. A máa ní òye tó yẹ ká ní tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àá rí báwọn ìlànà yẹn ò ṣe ní jẹ́ ká kó síṣòro àti bí wọ́n ṣe ń jẹ́ ká ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé, ṣé ìlànà Bíbélì ni mo fi ń ṣe àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe? Tó bá sì ti pẹ́ díẹ̀ tí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo sì ti ń wá sípàdé, kí ló dé tí mi ò tíì ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, kí n sì ṣèrìbọmi? Tí mo bá sì ti ṣèrìbọmi, ṣé mò ń já fáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni? Ṣé àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe fi hàn pé ìlànà Bíbélì ló ń darí mi? Ṣé bí Jésù ṣe máa ń ṣe sáwọn èèyàn lèmi náà máa ń ṣe sí wọn? Tá a bá rí i pé àwọn ibì kan wà tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe, ẹ jẹ́ ká gba ìmọ̀ràn Jèhófà torí pé ìyẹn ló máa ‘ń sọ aláìmọ̀kan di ọlọ́gbọ́n.’—Sm. 19:7. w22.10 20 ¶8

Monday, September 23

Wọ́n á lọ sí ibi tí ẹ̀mí bá darí wọn sí.—Ìsík. 1:20.

Ìsíkíẹ́lì rí i pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lágbára gan-an. Nínú ìran tó rí, ó rí bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń darí àwọn áńgẹ́lì alágbára àtàwọn àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin gìrìwò tó wà lọ́run. (Ìsík. 1:21) Kí ni Ìsíkíẹ́lì wá ṣe? Ó sọ pé: “Nígbà tí mo rí i, mo dojú bolẹ̀.” Ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí yẹn bà á lẹ́rù débi pé ó dojú bolẹ̀. (Ìsík. 1:28) Torí náà, tí Ìsíkíẹ́lì bá ti ń rántí ìran àgbàyanu tó rí yẹn, ó máa ń jẹ́ kó dá a lójú pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ran òun lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ tí Ọlọ́run rán òun. Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Ọmọ èèyàn, dìde dúró kí n lè bá ọ sọ̀rọ̀.” Ohun tí Jèhófà sọ yìí àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ló fún Ìsíkíẹ́lì lókun láti dìde dúró. (Ìsík. 2:​1, 2) Lẹ́yìn ìgbà yẹn àti jálẹ̀ gbogbo àkókò tí Ìsíkíẹ́lì fi jíṣẹ́ Ọlọ́run, “ọwọ́” Ọlọ́run, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ń tọ́ ọ sọ́nà.—Ìsík. 3:22; 8:1; 33:22; 37:1; 40:1. w22.11 4 ¶7-8

Tuesday, September 24

Etí rẹ sì máa gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ.—Àìsá. 30:21.

Wòlíì Àìsáyà fi Jèhófà wé olùkọ́ kan tó ń tẹ̀ lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ lẹ́yìn, tó ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, tó sì ń sọ ibi tí wọ́n máa gbà kí wọ́n má bàa ṣìnà. Lónìí, àwa náà ń gbọ́ ohùn Ọlọ́run lẹ́yìn wa. Lọ́nà wo? Látinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ti wà tipẹ́tipẹ́. Torí náà, tá a bá ń ka Bíbélì, ṣe ló dà bí ìgbà tá à ń gbọ́ ohùn Ọlọ́run láti ẹ̀yìn wa. (Àìsá. 51:4) Báwo la ṣe lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ látinú ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń fún wa? Kíyè sí i pé Àìsáyà sọ ọ̀nà méjì tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, ó ní “èyí ni ọ̀nà.” Ìkejì, ó ní “ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” Ká kàn mọ “ọ̀nà” tó yẹ ká máa rìn nìkan ò tó, ó tún yẹ ká máa “rìn nínú rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àlàyé tí ètò rẹ̀ ń ṣe máa ń jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ sílò. Torí náà, tá a bá fẹ́ máa fara dà á nìṣó, ká sì máa láyọ̀ bá a ṣe ń sin Jèhófà, a gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan méjèèjì tá a sọ yìí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wa. w22.11 11 ¶10-11

Wednesday, September 25

Lẹ́yìn tí mo bá lọ, àwọn aninilára ìkookò máa wọlé sáàárín yín.—Ìṣe 20:29.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ lára àwọn àpọ́sítélì Jésù kú, àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà wọnú ìjọ Kristẹni. (Mát. 13:​24-27, 37-39) Wọ́n sọ “àwọn ọ̀rọ̀ békebèke láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:30) Ọ̀kan lára “àwọn ọ̀rọ̀ békebèke” táwọn Kristẹni afàwọ̀rajà yẹn fi ń kọ́ni ni pé Jésù ò fi ara ẹ̀ rúbọ “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, kó lè ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀” bí Bíbélì ṣe sọ. Àmọ́ wọ́n ń kọ́ni pé Jésù gbọ́dọ̀ fi ara ẹ̀ rúbọ léraléra. (Héb. 9:​27, 28) Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gba ẹ̀kọ́ èké yìí gbọ́. Wọ́n máa ń péjọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé, nígbà míì lójoojúmọ́, kí wọ́n lè ṣe ààtò kan tí wọ́n ń pè ní “Máàsì.” Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì míì kì í ṣe é lemọ́lemọ́, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ ìjọ wọn ni ò mọ ìdí tí Jésù ṣe fi ara ẹ̀ rúbọ. w23.01 21 ¶5

Thursday, September 26

Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa pín ohun tí ẹ ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì.—Héb. 13:16.

Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Jésù máa jí àwọn tó ti kú dìde, ó sì máa sọ gbogbo àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn di pípé. Lẹ́yìn ìdánwò ìkẹyìn, àwọn tí Jèhófà bá sọ pé wọ́n jẹ́ olódodo ló máa “jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.” (Sm. 37:​10, 11, 29) Torí náà, “ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn” máa “di asán.” Ìyẹn mà múnú wa dùn gan-an o. (1 Kọ́r. 15:26) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó dá wa lójú pé a máa gbé ayé títí láé. Ìrètí tá a ní yìí máa mú ká jẹ́ olóòótọ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan nira yìí. Kì í kàn ṣe torí pé ó wù wá láti wà láàyè títí láé ló ṣe yẹ ká máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti Jésù ni pé a nífẹ̀ẹ́ wọn tọkàntọkàn. (2 Kọ́r. 5:​14, 15) Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù, ìyẹn ń jẹ́ ká máa fara wé wọn, ká sì máa wàásù fáwọn èèyàn nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. (Róòmù 10:​13-15) Torí náà, tá ò bá mọ tara wa nìkan, inú Jèhófà máa dùn sí wa, ó sì máa di ọ̀rẹ́ wa títí láé. w22.12 6-7 ¶15-16

Friday, September 27

Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.—2 Tím. 3:12.

Tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa, ó lè má ṣeé ṣe fún wa mọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tó ń fún wa láyọ̀. Inú wa máa ń dùn tá a bá ń pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará déédéé, tá à ń wàásù níbi gbogbo, tá a sì ń ṣe àwọn nǹkan míì láìbẹ̀rù pé ọlọ́pàá lè mú wa. Táwọn aláṣẹ ò bá jẹ́ ká ṣe àwọn nǹkan yẹn mọ́, ẹ̀rù lè máa bà wá torí a ò mọ ohun tí wọ́n lè ṣe sí wa. Kò sóhun tó burú tó bá ń ṣe wá bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó yẹ ká wà lójúfò torí Jésù sọ pé inúnibíni lè mú káwọn ọmọlẹ́yìn òun kọsẹ̀. (Jòh. 16:​1, 2) Lóòótọ́, Jésù sọ pé ká máa retí inúnibíni, síbẹ̀ ó fi dá wa lójú pé a ṣì lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Jòh. 15:20; 16:33) Tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa, ẹ̀ka ọ́fíìsì àtàwọn alàgbà lè sọ fún wa pé ká ṣe àwọn nǹkan kan. Àwọn ohun tí wọ́n bá ní ká ṣe máa dáàbò bò wá, wọ́n máa ń jẹ́ ká rí ìwé àti fídíò tó dá lórí Bíbélì gbà, wọ́n sì máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa wàásù nìṣó débi tí àyè bá gbà wá dé. Torí náà, rí i pé ò ń tẹ̀ lé àwọn ohun tí wọ́n bá sọ. (Jém. 3:17) Bákan náà, o ò gbọ́dọ̀ sọ ohunkóhun nípa àwọn ará fáwọn tí ò yẹ kó o sọ ọ́ fún.—Oníw. 3:7. w22.12 20-21 ¶14-16

Saturday, September 28

Máa ṣiṣẹ́ kára bẹ́ẹ̀.—Héb. 6:11.

Lónìí, Jésù ṣì ń darí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Jésù ń mú ìlérí tó ṣe fún wọn ṣẹ pé òun máa wà pẹ̀lú wọn. Jésù ń lo ètò Ọlọ́run láti dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ń fún wa láwọn nǹkan tá a nílò láti ṣiṣẹ́ náà. (Mát. 28:​18-20) Tá a bá ń ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni, à ń pa àṣẹ Jésù mọ́ nìyẹn, èyí sì ń jẹ́ ká wà lójúfò bá a ṣe ń retí ìgbà tí Jèhófà máa pa ayé búburú yìí run. Torí náà, tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Hébérù 6:​11, 12, a ò ní sọ̀rètí nù “títí dé òpin.” Jèhófà ti yan ọjọ́ àti wákàtí tó máa pa ayé búburú Sátánì yìí run. Tó bá dìgbà yẹn, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà ti sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa ayé tuntun ló máa jẹ́ kó ṣẹ láì ku ẹyọ kan. Nígbà míì, ó máa ń ṣe wá bíi pé ìgbà tí Jèhófà máa pa ayé búburú yìí run ti ń pẹ́ jù. Àmọ́, ó dájú pé ọjọ́ Jèhófà “kò ní pẹ́ rárá!” (Háb. 2:3) Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá “máa retí Jèhófà,” àá sì “dúró de Ọlọ́run ìgbàlà [wa].”—Míkà 7:7. w23.02 19 ¶15-16

Sunday, September 29

Kò sí ẹni tí a lè fi ọ́ wé.—Sm. 40:5.

Tẹ́nì kan bá ń gun òkè, ohun tó fẹ́ ni pé kóun gùn ún dé òkè pátápátá. Àmọ́ bó ṣe ń gùn ún lọ, àwọn ibì kan wà tó ti lè dúró kó sì wo àwọn ohun tó wà láyìíká ibẹ̀. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká máa wáyè ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Ká tó lọ sùn lálẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti ṣe fún mi lónìí? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro tí mo ní ò tíì lọ, báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn mí lọ́wọ́ láti fara dà á?’ Wò ó bóyá wàá rí ohun tí Jèhófà ṣe fún ẹ, bí ò tiẹ̀ ju ẹyọ kan lọ. Òótọ́ ni pé o lè máa gbàdúrà pé kí ìṣòro ẹ tán. (Fílí. 4:6) Àmọ́, ó yẹ ká tún máa rántí àwọn ohun rere tí Jèhófà ń ṣe fún wa báyìí. A mọ̀ pé Jèhófà ti ṣèlérí pé òun ò ní dá wa dá ìṣòro wa, òun á fún wa lókun ká lè fara dà á. Torí náà, máa dúpẹ́ gbogbo oore tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.—Jẹ́n. 41:​51, 52. w23.01 19 ¶17-18

Monday, September 30

Ẹ dúró de ìgbà tí ọjọ́ Jèhófà máa wà níhìn-ín.—2 Pét. 3:12.

Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé bí mo ṣe ń gbé ìgbé ayé mi fi hàn pé mo gbà pé ayé burúkú yìí máa tó pa run? Ṣé ìpinnu tí mò ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ lílọ sí Yunifásítì àti iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ fi hàn pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù sí mi? Ṣé mo nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa pèsè fún èmi àti ìdílé mi?’ Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó, tó bá rí i pé à ń gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ òun mu. (Mát. 6:​25-27, 33; Fílí. 4:​12, 13) Ó ṣe pàtàkì ká máa yẹ èrò wa wò déédéé, ká sì máa ṣàtúnṣe tó bá yẹ. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́r. 13:5) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa yí èrò wa pa dà. Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká máa ronú bí Ọlọ́run ṣe ń ronú, ká sì máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́.—1 Kọ́r. 2:​14-16. w23.01 9 ¶5-6

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́