October
Tuesday, October 1
Màá . . . yìn ọ́ láàárín ìjọ.—Sm. 22:22.
Tá a bá wà nípàdé, a lè fi hàn pé a fẹ́ káwọn ará gbádùn ìpàdé tá a bá jọ ń kọrin, tá a sì ń jẹ́ kí ìdáhùn wa gbé wọn ró. Ó máa ń ṣòro fáwọn ará wa kan láti kọrin, kí wọ́n sì dáhùn tí wọ́n bá wà nípàdé. Ṣé bó ṣe rí fún ìwọ náà nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè wo ohun táwọn kan tó nírú ìṣòro tó o ní yìí ti ṣe kí wọ́n lè borí ẹ̀. Àwọn kan ti rí i pé ohun tó dáa ni téèyàn bá ń fayọ̀ kọrin. Ohun tó yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń kọrin Ìjọba Ọlọ́run ni pé a fẹ́ yin Jèhófà lógo. Torí náà, máa múra orin tá a máa kọ nípàdé sílẹ̀ bó o ṣe máa múra àwọn apá ìpàdé yòókù, kó o sì wo bí àwọn ọ̀rọ̀ inú orin náà ṣe bá ohun tí wọ́n máa jíròrò nípàdé mu. Lẹ́yìn náà, pọkàn pọ̀ sórí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà dípò kó o pọkàn pọ̀ sórí orin tí o ò mọ̀ ọ́n kọ dáadáa. Ká sòótọ́, kì í rọrùn fáwọn kan láti máa dáhùn nípàdé. Àmọ́ kí la lè ṣe? Máa dáhùn nípàdé déédéé. Fi sọ́kàn pé, kò yẹ kí ìdáhùn ẹ gùn jù, ó sì yẹ kó ṣe tààràtà. Jèhófà mọyì gbogbo ohun tá a bá ṣe ká lè máa yìn ín láàárín ìjọ. w22.04 7-8 ¶12-15
Wednesday, October 2
Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù.—Héb. 13:6.
Ọ̀rọ̀ náà “olùrànlọ́wọ́” ń sọ nípa ẹnì kan tó sáré lọ ṣèrànwọ́ fún ẹnì kan tó ń sunkún pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́. Torí náà, fojú inú wo bí Jèhófà ṣe ń tètè ran ẹni tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́. Ó dájú pé àpèjúwe yìí máa jẹ́ kó o gbà pé Olùrànlọ́wọ́ ni Jèhófà, ó sì máa ń wù ú láti tètè ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, tí Jèhófà bá ràn wá lọ́wọ́, ó máa ń jẹ́ ká fara da ìṣòro wa, ká sì máa láyọ̀. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wa? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo ìwé Àìsáyà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà ní kí Àìsáyà kọ ló kan àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀rọ̀ tó yé àwa èèyàn dáadáa ni Àìsáyà sábà máa ń lò láti fi ṣàlàyé ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú Àìsáyà orí ọgbọ̀n (30). Nínú orí yìí, Àìsáyà lo àwọn ọ̀rọ̀ tó ń mú kí nǹkan yéni nígbà tó ń ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe máa ń ran àwa èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́, (1) ó sọ pé Jèhófà máa tẹ́tí sí wa, ó sì máa ń gbọ́ àdúrà wa, (2) ó máa ń tọ́ wa sọ́nà àti (3) ó máa ń ṣe àwọn nǹkan rere fún wa báyìí, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. w22.11 8 ¶2-3
Thursday, October 3
Má bẹ̀rù àwọn nǹkan tí o máa tó jìyà rẹ̀. . . . Jẹ́ olóòótọ́, kódà títí dójú ikú, màá sì fún ọ ní adé ìyè.—Ìfi. 2:10.
Nígbà tí Jésù ránṣẹ́ sí ìjọ tó wà ní Símínà àti Filadéfíà, ó sọ fún àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀ pé kí wọ́n má bẹ̀rù inúnibíni torí wọ́n máa gba èrè lọ́dọ̀ Jèhófà tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́. (Ìfi. 3:10) A gbọ́dọ̀ máa retí inúnibíni, ká sì múra tán láti fara dà á. (Mát. 24:9, 13; 2 Kọ́r. 12:10) Ìwé Ìfihàn sọ fún wa pé wọ́n máa ṣe inúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run ní àkókò tiwa yìí, ìyẹn ní “ọjọ́ Olúwa.” (Ìfi. 1:10) Ìfihàn orí 12 sọ pé ogun ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run kété lẹ́yìn tí Jésù di Ọba. Máíkẹ́lì, ìyẹn Jésù Kristi tí Ọlọ́run ṣe lógo àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù jà. (Ìfi. 12:7, 8) Ohun tó yọrí sí ni pé, Jésù ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, ó jù wọ́n sí ayé, ìyẹn sì mú kí ìyà rẹpẹtẹ máa jẹ ayé àtàwọn tó ń gbé inú ẹ̀.—Ìfi. 12:9, 12. w22.05 5 ¶12-13
Friday, October 4
Kò sí ojúsàájú lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.—2 Kíró. 19:7.
Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣèdájọ́ òdodo, ó sì máa ń dájọ́ lọ́nà tó tọ́. Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú rárá. Kì í ṣe bí ẹnì kan ṣe rí, bó ṣe lówó tó, bó ṣe gbajúmọ̀ tó tàbí bó ṣe mọ nǹkan ṣe tó ni Jèhófà máa ń wò tó bá fẹ́ dárí ji ẹni náà. (1 Sám. 16:7; Jém. 2:1-4) Ìdí sì ni pé kò sẹ́ni tó lè fúngun mọ́ Jèhófà tàbí kó fún un ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Jèhófà kì í fìyà jẹ ẹnì kan torí pé inú ń bí i tàbí torí pé ọ̀rọ̀ onítọ̀hún ti sú u. (Ẹ́kís. 34:7) Kò sí àní-àní pé Jèhófà ni Adájọ́ tó dáa jù lọ torí pé ó mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan wa àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa. (Diu. 32:4) Àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù gbà pé bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá ṣàrà ọ̀tọ̀. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé láwọn ibì kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, wọ́n lo ọ̀rọ̀ Hébérù tó jẹ́ pé “ibi tí wọ́n bá ti ń sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan nìkan ni wọ́n ti máa ń lo irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Wọn kì í lò ó tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí ẹnì kan ṣe dárí ji ẹlòmíì.” Jèhófà nìkan ló lágbára láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà pátápátá. w22.06 4 ¶10-11
Saturday, October 5
Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀; kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.—Òwe 22:6.
Tó o bá ń dá tọ́mọ tàbí tí ọkọ ẹ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mọ̀ dájú pé àpẹẹrẹ rere tó o fi lélẹ̀ ń fún àwọn tẹ́ ẹ jọ ń sin Jèhófà lókun. Tó o bá rí i pé ọmọ ẹ ò fẹ́ sin Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ti kọ́ ọ, kí ló yẹ kó o ṣe? Rántí pé ó máa ń gba àkókò láti tọ́ ọmọ kan yanjú. Tó o bá gbin èso kan, o lè máa rò ó pé ṣé èso náà máa dàgbà di igi táá máa so èso? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ò lè mọ̀ bóyá igi náà máa so èso, wàá máa bomi rin ín déédéé kó lè dàgbà dáadáa. (Máàkù 4:26-29) Lọ́nà kan náà, ìyá kan lè máa rò pé bóyá lòun ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ kóun ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ òun kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. O ò lè pinnu ohun táwọn ọmọ ẹ máa ṣe. Àmọ́ tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti kọ́ wọn nípa Jèhófà, ìyẹn máa fún wọn láǹfààní láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. w22.04 19-20 ¶16-17
Sunday, October 6
Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun, ẹ̀mí ìgbéraga ló sì ń ṣáájú ìkọ̀sẹ̀.—Òwe 16:18.
Nígbà tí Sólómọ́nì ń fi òótọ́ ọkàn sin Jèhófà, ojú tó tọ́ ló fi ń wo ara ẹ̀. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó gbà pé òun ò gbọ́n tó, ó sì bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà. (1 Ọba 3:7-9) Nígbà tí Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba, ó gbà pé ó léwu téèyàn bá ń gbéra ga. Ó ṣeni láàánú pé nígbà tó yá, Sólómọ́nì ò fi ìmọ̀ràn tóun fúnra ẹ̀ sọ sílò mọ́. Bó ṣe ń jọba lọ, ó di agbéraga, kò sì ka òfin Ọlọ́run sí mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn òfin yẹn sọ pé àwọn ọba Ísírẹ́lì ò ‘gbọ́dọ̀ kó ìyàwó rẹpẹtẹ jọ fún ara wọn, kí ọkàn wọn má bàa yí pa dà.’ (Diu. 17:17) Àmọ́ Sólómọ́nì ò ka òfin yẹn sí. Ṣe ló fẹ́ ọgọ́rùn-ún méje (700) ìyàwó àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) wáhàrì. (1 Ọba 11:1-3) Sólómọ́nì lè rò pé “kò séwu kankan.” Àmọ́ nígbà tó yá, ó jìyà ẹ̀ torí pé ó fi Jèhófà sílẹ̀.—1 Ọba 11:9-13. w22.05 23 ¶12
Monday, October 7
“Ìgbàgbọ́ yóò mú kí olódodo mi wà láàyè” àti pé “tó bá fà sẹ́yìn, inú mi ò ní dùn sí i.”—Héb. 10:38.
Lónìí, ìpinnu pàtàkì kan wà tí gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe. Ìpinnu náà ni pé, ṣé Jèhófà Ọlọ́run Alákòóso ayé àtọ̀run ni wọ́n máa tì lẹ́yìn ni àbí Sátánì Èṣù ọ̀tá rẹ̀ tó burú jù lọ? Ìkan nínú méjèèjì lèèyàn gbọ́dọ̀ mú. Ìpinnu tí wọ́n bá ṣe ló máa sọ bóyá wọ́n á wà láàyè títí láé tàbí wọ́n á pa run. (Mát. 25:31-33, 46) Nígbà “ìpọ́njú ńlá,” wọ́n máa sàmì sí wọn kí wọ́n lè la ìpọ́njú náà já tàbí kí wọ́n pa run. (Ìfi. 7:14; 14:9-11; Ìsík. 9:4, 6) Tó bá jẹ́ pé àkóso Jèhófà lo tì lẹ́yìn, ìpinnu tó dáa lo ṣe yẹn. Torí náà, ó yẹ kó o ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ káwọn náà lè ṣe irú ìpinnu yẹn. Àwọn nǹkan rere ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń ti àkóso Jèhófà lẹ́yìn. Kò yẹ ká gbàgbé àwọn òtítọ́ pàtàkì yẹn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa túbọ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó. Yàtọ̀ síyẹn, a lè lo ohun tá a kọ́ nínú ìwé náà láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá sin Jèhófà, kí wọ́n má sì fi í sílẹ̀. w22.05 15 ¶1-2
Tuesday, October 8
Aláyọ̀ ni yín tí àwọn èèyàn bá . . . parọ́ oríṣiríṣi ohun burúkú mọ́ yín.—Mát. 5:11.
Jèhófà ló yẹ ká máa tẹ́tí sí, kì í ṣe àwọn ọ̀tá wa. Jóòbù tẹ́tí sí ohun tí Jèhófà sọ fún un. Jèhófà bá Jóòbù fèròwérò, ṣe ló dà bí ìgbà tí Ọlọ́run ń sọ fún un pé: ‘Mo mọ gbogbo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Ṣé o rò pé mi ò ní lè yọ ẹ́ nínú ìṣòro yẹn ni?’ Jóòbù fi ìrẹ̀lẹ̀ dá Jèhófà lóhùn, ó sì fi hàn pé òun mọyì àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún òun. Ó sọ pé: “Etí mi ti gbọ́ nípa rẹ, àmọ́ ní báyìí, mo ti fi ojú mi rí ọ.” (Jóòbù 42:5) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ inú eérú ni Jóòbù jókòó sí nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yẹn, tí eéwo sì bò ó látorí dé àtẹ́lẹsẹ̀. Síbẹ̀, Jèhófà jẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, ó sì jẹ́ kó dá a lójú pé inú òun dùn sí i. (Jóòbù 42:7, 8) Lónìí, àwọn èèyàn lè bú wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ hùwà sí wa bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Wọ́n lè fẹ́ bà wá lórúkọ jẹ́ tàbí kí wọ́n gbìyànjú láti ba orúkọ ètò Ọlọ́run jẹ́. Ìtàn Jóòbù kọ́ wa pé Jèhófà fọkàn tán wa pé a máa jẹ́ olóòótọ́ sí òun lójú àdánwò. w22.06 24 ¶15-16
Wednesday, October 9
Àkókò ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn ti tó.—Ìfi. 19:7.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ariwo ayọ̀ má sọ lọ́run nígbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run, ohun míì máa ṣẹlẹ̀ tó máa mú ayọ̀ tó ju ìyẹn lọ wá. (Ìfi. 19:1-3) Nǹkan náà ni “ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” ó sì wà lára àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù nínú ìwé Ìfihàn. Gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì máa ti wà lọ́run kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ìgbà yẹn ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà máa ṣègbéyàwó. (Ìfi. 21:1, 2) Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà máa wáyé lẹ́yìn tí ogun Amágẹ́dọ́nì bá ti parí, tí Ọlọ́run sì ti pa gbogbo àwọn ọ̀tá ẹ̀ run. (Sm. 45:3, 4, 13-17) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà? Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ níbi ìgbéyàwó ọkùnrin kan àti obìnrin kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ níbi ìgbéyàwó ìṣàpẹẹrẹ yìí. Jèhófà máa so Jésù Kristi Ọba àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì “ìyàwó” rẹ̀ pọ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí ló máa mú kí ìjọba tuntun náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé fún ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún.—Ìfi. 20:6. w22.05 17 ¶11-13
Thursday, October 10
Aláyọ̀ ni ẹrú yẹn tí ọ̀gá rẹ̀ bá . . . rí i tó ń ṣe bẹ́ẹ̀!—Mát. 24:46.
Jésù sọ pé tó bá di àkókò òpin, òun máa yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ wa. (Mát. 24:45) Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé ẹrú náà ń ṣiṣẹ́ kára. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn. Jésù ń lo àwùjọ kéréje àwọn ọkùnrin tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn yìí láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ àwa àtàwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ “ní àkókò tó yẹ.” Àwọn ọkùnrin yìí ò jọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ wa. (2 Kọ́r. 1:24) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà pé Jésù Kristi ni “aṣáájú àti aláṣẹ” àwa èèyàn Ọlọ́run. (Àìsá. 55:4) Láti ọdún 1919, ẹrú olóòótọ́ ti ṣe oríṣiríṣi ìwé tó fún àwọn tó fẹ́ mọ Ọlọ́run láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n lè mọ òtítọ́. Lọ́dún 1921, ẹrú náà ṣe ìwé Duru Ọlọrun lédè Gẹ̀ẹ́sì (èyí tá a tẹ̀ lédè Yorùbá lọ́dún 1930) láti ran àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, wọ́n ṣe àwọn ìwé míì. Èwo nínú àwọn ìwé yìí ló ràn ẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ Bàbá wa ọ̀run, tó sì jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? w22.07 10 ¶9-10
Friday, October 11
Wàá fi mí sí iwájú rẹ títí láé.—Sm. 41:12.
Jèhófà ló lawọ́ jù lọ láyé àtọ̀run. Tó o bá fún Jèhófà ní nǹkan, ohun tó máa fún ẹ pa dà máa pọ̀ gan-an ju ohun tó o fún un lọ. (Máàkù 10:29, 30) Lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa jẹ́ kó o gbádùn ayé ẹ gan-an, ó sì máa san èrè fún ẹ. Kódà nínú ayé burúkú yìí, ó máa jẹ́ kó o gbé ìgbé ayé aláyọ̀. Àmọ́, o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà ni o. Títí láé ni wàá máa sin Bàbá rẹ ọ̀run, ìfẹ́ tó wà láàárín ìwọ àti Jèhófà á sì túbọ̀ máa lágbára. Torí náà, ó dájú pé wàá wà láàyè títí láé, bí Jèhófà ti ń bẹ láàyè. Nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà tó o sì ṣèrìbọmi, àǹfààní ńlá lo ní yẹn láti fún Bàbá rẹ ọ̀run lóhun kan tó ṣeyebíye. Jèhófà ló fún ẹ ní gbogbo ohun tó dáa tó o ní àti gbogbo nǹkan tó ń múnú ẹ dùn nígbèésí ayé ẹ. Ìwọ náà lè fún Jèhófà tó ni ayé àti ọ̀run ní nǹkan tí ò ní, ìyẹn ìjọsìn tó tọkàn wá. (Jóòbù 1:8; 41:11; Òwe 27:11) Àbí ohun míì wà tó dáa jùyẹn lọ tó o lè fìgbésí ayé ẹ ṣe? w23.03 6 ¶16-17
Saturday, October 12
Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Tó bá ń kíyè sára, tó sì ń pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.—Sm. 119:9.
Tí ọ̀dọ́ kan bá ti ń dàgbà, ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ á máa lágbára lọ́kàn ẹ̀, àwọn ẹlòmíì sì lè máa yọ ọ́ lẹ́nu pé kó ṣèṣekúṣe. Ohun tí Sátánì sì fẹ́ kó o ṣe nìyẹn. Kí ni ò ní jẹ́ kó o ṣèṣekúṣe? (1 Tẹs. 4:3, 4) Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà tó o bá ń gbàdúrà, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ lókun. (Mát. 6:13) Rántí pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, kì í ṣe pé ó máa fìyà jẹ ẹ́. (Sm. 103:13, 14) Má ṣe rò pé o lè dá yanjú ìṣòro ẹ. Sọ ìṣòro tó o ní fáwọn òbí ẹ. Ó lè má rọrùn láti sọ ọ̀rọ̀ ara ẹ fún ẹlòmíì, àmọ́ ó ṣe pàtàkì pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń ka Bíbélì tó o sì ń ronú lórí àwọn ìlànà tó wà níbẹ̀, wàá lè ṣèpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn. Wàá rí i pé kò dìgbà tó o bá rí òfin pàtó kan kó o tó ṣèpinnu torí pé wàá ti mọ ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan. w22.08 5 ¶10-12
Sunday, October 13
Tí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, . . . ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́.—1 Tím. 5:8.
Àwọn olórí ìdílé tó jẹ́ Kristẹni gbà pé ojúṣe pàtàkì ni láti pèsè àwọn nǹkan tí ìdílé wọn nílò. Tó o bá jẹ́ olórí ìdílé, o lè máa ṣàníyàn pé báwo lo ṣe máa pèsè oúnjẹ, tó o sì máa sanwó ilé. O sì lè máa bẹ̀rù pé tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ pẹ́rẹ́n, o lè má rí iṣẹ́ míì. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé tó o bá ṣe àwọn àyípadà nínú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ẹ, owó táá máa wọlé fún ẹ ò ní tó ẹ ná. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò sin Jèhófà mọ́ torí pé Sátánì ti lo irú ọgbọ́n yìí láti dẹ́rù bà wọ́n. Sátánì máa ń fẹ́ ká gbà pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé kì í dá sí bá a ṣe máa pèsè fún ìdílé wa. Torí náà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé gbogbo ohun tó bá gbà la máa ṣe kí iṣẹ́ tá à ń ṣe má bàa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́ kódà tó bá tiẹ̀ máa pa ìjọsìn wa lára. w22.06 15 ¶5-6
Monday, October 14
A ní ìrètí yìí bí ìdákọ̀ró fún ọkàn, ó dájú, ó fìdí múlẹ̀.—Héb. 6:19.
A tún mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ “aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Ẹ́kís. 34:6) Jèhófà tún nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo. (Àìsá. 61:8) Ó máa ń dùn ún tá a bá ń jìyà, ó sì ṣe tán láti mú gbogbo ìyà náà kúrò ní àkókò tó tọ́ lójú ẹ̀. (Jer. 29:11) À ń fojú sọ́nà fún ìgbà ọ̀tun yẹn! Ìdí nìyẹn tá a fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an! Nǹkan míì wo ló mú ká nífẹ̀ẹ́ òtítọ́? Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí torí pé a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Bí ìdákọ̀ró kì í ṣeé jẹ́ kí omi gbé ọkọ̀ ojú omi lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìrètí tá a ní pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa kì í jẹ́ kí ìṣòro bò wá mọ́lẹ̀. Nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìrètí táwọn ẹni àmì òróró ní pé ọ̀run làwọn ń lọ àti bí wọ́n ṣe mọyì ẹ̀ tó. Àmọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn tún kan àwọn Kristẹni tó nírètí pé àwọn máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè. (Jòh. 3:16) Ó dájú pé ìrètí tá a ní pé a máa rí ìyè àìnípẹ̀kun ti mú káyé wa dáa sí i. w22.08 14-15 ¶3-5
Tuesday, October 15
Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ìbínú.—Éfé. 4:26.
Ìfẹ́ ló máa ń jẹ́ ká fọkàn tánni. Kọ́ríńtì Kìíní orí 13 sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa bí ìfẹ́ ṣe lè mú ká fọkàn tán àwọn ará tàbí bá a ṣe lè pa dà fọkàn tán àwọn ará tí wọ́n bá tiẹ̀ ti ṣohun tó dùn wá. (1 Kọ́r. 13:4-8) Bí àpẹẹrẹ, ẹsẹ kẹrin sọ pé “ìfẹ́ máa ń ní sùúrù àti inú rere.” Jèhófà máa ń mú sùúrù fún wa tá a bá tiẹ̀ ṣẹ̀ ẹ́. Torí náà, ó yẹ ká máa ní sùúrù fáwọn ará tí wọ́n bá tiẹ̀ ṣe ohun kan tàbí sọ ohun tó dùn wá. Ẹsẹ karùn-ún tún sọ pé: “[Ìfẹ́] kì í tètè bínú. Kì í di èèyàn sínú.” Kò yẹ ká gbé ọ̀rọ̀ kan sọ́kàn, ká má sì gbàgbé ẹ̀, ká wá máa fi hùwà sí onítọ̀hún. Oníwàásù 7:9 sọ pé ká “má ṣe máa yára bínú.” Ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ni káwa náà máa fi wò wọ́n. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn, kì í sì í kọ àṣìṣe wọn sílẹ̀, torí náà kò yẹ káwa náà ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 130:3) Dípò ká máa wo àṣìṣe wọn, ìwà tó dáa tí wọ́n ní ló yẹ ká máa wò.—Mát. 7:1-5. w22.09 3-4 ¶6-7
Wednesday, October 16
Àkókò wàhálà máa wáyé.—Dán. 12:1.
Ìwé Dáníẹ́lì jẹ́ ká mọ bí àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lásìkò òpin yìí ṣe máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra wọn. Bí àpẹẹrẹ, Dáníẹ́lì 12:1 sọ pé Jésù Kristi tó jẹ́ Máíkẹ́lì “dúró nítorí àwọn èèyàn” Ọlọ́run. Apá kan lára àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti ṣẹ nígbà tí Jésù di Ọba Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914. Àmọ́ nínú ìran tí Dáníẹ́lì rí, áńgẹ́lì kan tún sọ fún un pé Jésù “máa dìde” ní ‘àkókò wàhálà, èyí tí irú rẹ̀ kò wáyé rí látìgbà tí orílẹ̀-èdè ti wà títí di àkókò yẹn.’ “Àkókò wàhálà” náà ni Mátíù 24:21 pè ní “ìpọ́njú ńlá.” Jésù máa dìde láti gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ ní òpin àkókò wàhálà náà, ìyẹn nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Ìwé Ìfihàn pe àwọn èèyàn tí Jésù máa gbèjà ní ogunlọ́gọ̀ èèyàn “tó wá látinú ìpọ́njú ńlá náà.”—Ìfi. 7:9, 14. w22.09 21 ¶4-5
Thursday, October 17
Màá pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ mí rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.—Ẹ́kís. 32:33.
Ọlọ́run ṣì lè pa orúkọ àwọn tó ti wà nínú ìwé ìyè rẹ́. Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà kọ orúkọ náà sílẹ̀ lọ́nà tó ṣeé pa rẹ́. (Ìfi. 3:5, àlàyé ìsàlẹ̀) A gbọ́dọ̀ rí i dájú pé orúkọ wa wà nínú ìwé yìí títí dìgbà tí Ọlọ́run máa kọ ọ́ lọ́nà tí kò ní ṣeé pa rẹ́ mọ́. Àwùjọ àwọn kan tí orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè ni àwọn tí Jèhófà yàn láti bá Jésù ṣàkóso lọ́run. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn “alábàáṣiṣẹ́” rẹ̀ sọ̀rọ̀ nílùú Fílípì, ó sọ pé orúkọ àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n máa bá Jésù ṣàkóso ti wà nínú ìwé ìyè. (Fílí. 4:3) Àmọ́ tí wọ́n bá fẹ́ kí orúkọ wọn máa wà nínú ìwé yẹn títí lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ títí dópin. Torí náà, ìgbà tí wọ́n bá gba èdìdì ìkẹyìn ni orúkọ wọn máa wà nínú ìwé ìyè títí láé, ìyẹn sì máa ṣẹlẹ̀ kí wọ́n tó kú tàbí kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀.—Ìfi. 7:3. w22.09 14 ¶3; 15 ¶5-6
Friday, October 18
Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!—Lúùkù 11:28.
Ká sọ pé ẹnì kan se oúnjẹ tó o fẹ́ràn gan-an, àmọ́ torí pé ò ń kánjú tàbí torí pé ibòmíì lọkàn ẹ wà, ṣe lo kàn sáré kó oúnjẹ náà mì. Àmọ́ lẹ́yìn tó o parí oúnjẹ náà, ó wá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò bá ti fara balẹ̀ jẹ ẹ́ kó o lè gbádùn ẹ̀. Ṣé irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí? Wá bi ara ẹ pé, ṣé ìgbà kan wà tó o sáré ka Bíbélì, dípò kó o fara balẹ̀ ronú nípa ohun tó o kà kó o lè gbádùn ẹ̀? Torí náà, máa fara balẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, fojú inú wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀, wò ó bíi pé ò ń gbọ́ àwọn ìró tó ń jáde níbẹ̀, kó o sì ronú lórí ohun tó o kà. Tó o bá ń ka Bíbélì bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ láyọ̀. Jésù yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kó lè máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ wa dáadáa lákòókò tó yẹ. (Mát. 24:45) Ẹrú olóòótọ́ máa ń rí i dájú pé gbogbo ìwé àti fídíò tí wọ́n ń ṣe dá lórí Bíbélì.—1 Tẹs. 2:13. w22.10 7-8 ¶6-8
Saturday, October 19
Àwọn ajọra-ẹni-lójú ti fi wá ṣẹ̀sín dé góńgó.—Sm. 123:4.
Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá dọjọ́ ìkẹyìn, àwọn tó ń fini ṣẹlẹ́yà máa pọ̀ gan-an. (2 Pét. 3:3, 4) Àwọn afiniṣẹ̀sín ń ṣohun tí wọ́n ń ṣe yìí torí ‘ohun tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu ló ń wù wọ́n.’ (Júùdù 7, 17, 18) Kí la lè ṣe tá ò bá fẹ́ fìwà jọ àwọn afiniṣẹ̀sín? Ohun tá a lè ṣe ni pé ká yẹra fún àwọn èèyàn tó bá ń ṣàríwísí ṣáá nípa gbogbo nǹkan. (Sm. 1:1) Ìyẹn ni pé a ò ní máa tẹ́tí sí àwọn apẹ̀yìndà, a ò sì ní máa ka ìwé wọn. A mọ̀ pé tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí gbogbo nǹkan, ká má fọkàn tán Jèhófà mọ́, ká sì máa kọminú sí ohun tí ètò ẹ̀ bá ń sọ fún wa. Torí náà, tá ò bá fẹ́ fìwà jọ àwọn afiniṣẹ̀sín, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń ṣàríwísí tí ètò Ọlọ́run bá fún wa ní ìtọ́ni tuntun kan tàbí tí wọ́n ṣàlàyé òye tuntun kan? Ṣé kì í ṣe ibi táwọn tó ń ṣàbójútó wa kù sí ni mo máa ń wò ṣáá?’ Torí náà, tá a bá tètè mú èrò tí ò tọ́ yìí kúrò lọ́kàn wa, inú Jèhófà máa dùn sí wa.—Òwe 3:34, 35. w22.10 20 ¶9-10
Sunday, October 20
Ilé Ísírẹ́lì ò ní tẹ́tí sí ọ.—Ìsík. 3:7.
Ẹ̀mí Ọlọ́run ran Ìsíkíẹ́lì lọ́wọ́ nígbà tó lọ jíṣẹ́ fún àwọn “olórí kunkun àti ọlọ́kàn líle” tó wà ní Ísírẹ́lì. Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Mo ti mú kí ojú rẹ le bí ojú wọn, mo sì mú kí iwájú orí rẹ le bí iwájú orí wọn. Mo ti mú kí iwájú orí rẹ dà bíi dáyámọ́ǹdì, ó le ju akọ òkúta lọ. Má bẹ̀rù wọn, má sì jẹ́ kí ojú wọn dẹ́rù bà ọ́.” (Ìsík. 3:8, 9) Ohun tí Jèhófà ń sọ fún Ìsíkíẹ́lì ni pé: ‘Má ṣe jẹ́ kí orí kunkun àwọn èèyàn náà mú kó o rẹ̀wẹ̀sì. Màá fún ẹ lágbára.’ Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí Ọlọ́run darí Ìsíkíẹ́lì nínú ìran, ó sì gbé e lọ síbi tó ti fẹ́ jíṣẹ́ Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ìsíkíẹ́lì sọ pé: “Ọwọ́ Jèhófà wà lára mi lọ́nà tó lágbára.” Ó gba wòlíì náà ní ọ̀sẹ̀ kan gbáko láti ronú nípa iṣẹ́ tó fẹ́ lọ jẹ́ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ìsík. 3:14, 15) Jèhófà darí Ìsíkíẹ́lì lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan, “ẹ̀mí wá wọ inú [rẹ̀].” (Ìsík. 3:23, 24) Ní báyìí, Ìsíkíẹ́lì ti gbára dì láti lọ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an. w22.11 4-5 ¶8-9
Monday, October 21
Jèhófà, báwo ló ṣe máa pẹ́ tó tí màá fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ àmọ́ tí o kò gbọ́? . . . Kí sì nìdí tí o fi fàyè gba ìnilára?—Háb. 1:2, 3.
Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló dé bá wòlíì Hábákúkù. Ìgbà kan wà tó rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ òun. Torí náà, ó gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà. Jèhófà dáhùn àdúrà àtọkànwá tí ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ yìí gbà. (Háb. 2:2, 3) Lẹ́yìn tí Hábákúkù ronú lórí bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn ẹ̀ là, ó tún pa dà láyọ̀. Ó wá dá a lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun, ó sì máa ran òun lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro yòówù kó dé bá òun. (Háb. 3:17-19) Kí la rí kọ́? Tí ìṣòro bá dé bá ẹ, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún un. Lẹ́yìn náà, fi sùúrù dúró dè é. Ó dájú pé Jèhófà máa fún ẹ lókun láti fara da ìṣòro náà. Tó o bá sì ti rọ́wọ́ Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ náà, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ lágbára. Torí náà, tíwọ náà bá túbọ̀ ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn ò ní jẹ́ kí ìṣòro tàbí iyèméjì mú kó o fi Jèhófà sílẹ̀.—1 Tím. 6:6-8. w22.11 15 ¶6-7
Tuesday, October 22
Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, o máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.—Lúùkù 23:43.
Jésù àtàwọn ọ̀daràn méjì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ ń jẹ̀rora bí wọ́n ṣe ń kú lọ. (Lúùkù 23:32, 33) Àwọn ọ̀daràn náà ń sọ̀rọ̀ burúkú sí Jésù. (Mát. 27:44; Máàkù 15:32) Àmọ́ ọ̀kan lára wọn yí pa dà. Ó sọ pé: “Jésù, rántí mi tí o bá dé inú Ìjọba rẹ.” Jésù wá fi ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ ojúmọ́ tòní dá a lóhùn. (Lúùkù 23:39-42) Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún ọ̀daràn náà mú ká ronú nípa bí ìgbésí ayé nínú Párádísè ṣe máa rí. A lè mọ bí nǹkan ṣe máa rí nínú Párádísè tá a bá wo bí àlàáfíà ṣe wà nígbà tí Ọba Sólómọ́nì ń ṣàkóso. Bíbélì sọ pé Jésù tóbi ju Sólómọ́nì lọ, ìyẹn sì jẹ́ ká gbà pé Jésù àtàwọn tó máa bá a ṣàkóso máa sọ ayé yìí di Párádísè. (Mát. 12:42) Torí náà, ó yẹ kí “àwọn àgùntàn mìíràn” mọ ohun tí wọ́n máa ṣe kí wọ́n lè gbé ayé títí láé nínú Párádísè.—Jòh. 10:16. w22.12 8 ¶1; 9 ¶4
Wednesday, October 23
Ó dájú pé ó máa ṣojúure sí ọ tí o bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́.—Àìsá. 30:19.
Àìsáyà fi dá wa lójú pé Jèhófà máa tẹ́tí sí wa tá a bá kígbe pé kó ràn wá lọ́wọ́, ó sì máa tètè gbọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wa. Àìsáyà tún sọ pé: “Ó máa dá ọ lóhùn ní gbàrà tó bá gbọ́ ọ.” Àwọn ọ̀rọ̀ tó dájú tí Àìsáyà sọ yìí rán wa létí pé ó máa ń wu Bàbá wa ọ̀run láti ran àwọn tó bá ń ké pè é lọ́wọ́. Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ yìí ló ń jẹ́ ká máa fara dà á, ká sì máa láyọ̀. Jèhófà máa ń tẹ́tí sí àdúrà ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Láwọn ẹsẹ tó ṣáájú nínú Àìsáyà orí 30, Àìsáyà lo ọ̀rọ̀ náà “yín” láti fi hàn pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Jèhófà ń bá sọ̀rọ̀, àmọ́ ní ẹsẹ 19, ó lo “ọ” láti fi hàn pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lòun ń bá sọ̀rọ̀. Àìsáyà sọ pé: “O ò ní sunkún rárá. Ó dájú pé ó máa ṣojúure sí ọ”; “ó máa dá ọ lóhùn.” Torí pé Jèhófà Bàbá wa nífẹ̀ẹ́ àwa ọmọ ẹ̀, ó máa ń bójú tó ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, ó sì ń gbọ́ àdúrà wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—Sm. 116:1; Àìsá. 57:15. w22.11 9 ¶5-6
Thursday, October 24
Ẹ máa ṣọ́ra bí ejò, síbẹ̀ kí ẹ jẹ́ ọlọ́rùn mímọ́ bí àdàbà.—Mát. 10:16.
Bí wọ́n tiẹ̀ ń ta kò wá, tá a bá ń wàásù tá a sì ń kọ́ni, ó máa ń fún wa láyọ̀, ọkàn wa sì máa balẹ̀. Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ táwọn aláṣẹ Júù sọ pé káwọn àpọ́sítélì má wàásù mọ́, àwọn àpọ́sítélì yẹn pinnu pé Ọlọ́run làwọn máa ṣègbọràn sí. Wọ́n ń wàásù nìṣó, iṣẹ́ yẹn sì ń fún wọn láyọ̀. (Ìṣe 5:27-29, 41, 42) Lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ fọgbọ́n wàásù tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa. Àmọ́ tá a bá ń ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe, ọkàn wa máa balẹ̀ pé à ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe àti pé à ń kéde ìhìn rere tó máa gbẹ̀mí là. Lásìkò tí nǹkan bá le gan-an, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o ṣì lè ní àlàáfíà tòótọ́. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, máa rántí pé àlàáfíà tó o nílò ni àlàáfíà tó jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló lè fúnni. Torí náà, gbára lé Jèhófà nígbà àjàkálẹ̀ àrùn, nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí ẹ. Má fi àwọn ará àti ètò Ọlọ́run sílẹ̀. Máa ronú nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ‘Ọlọ́run àlàáfíà máa wà pẹ̀lú ẹ.’—Fílí. 4:9. w22.12 21 ¶17-18
Friday, October 25
Ẹ gbé ìwà tuntun wọ̀.—Éfé. 4:24.
Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó gba iṣẹ́ àṣekára. Bí àpẹẹrẹ, ká tó lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò dáa, irú bí inú burúkú, ìbínú àti ìrunú, ó gba iṣẹ́ àṣekára. (Éfé. 4:31, 32) Kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti yí pa dà? Ohun tó lè mú kó ṣòro ni pé kì í rọrùn láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tó ti mọ́ wa lára. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn kan máa ń “tètè bínú,” wọ́n sì “[jẹ́] onínúfùfù.” (Òwe 29:22) Ká tó lè jáwọ́ nínú ìwà burúkú tó ti mọ́ wa lára, ó gba iṣẹ́ àṣekára láti yí pa dà kódà lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi. (Róòmù 7:21-23) Tó bá wù ẹ́ láti borí ìwà kan tí ò dáa, gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì nígbàgbọ́ pé á gbọ́ ẹ, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. (1 Jòh. 5:14, 15) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò ní mú ìwà burúkú náà kúrò lọ́nà ìyanu, á fún ẹ lókun kó o lè borí ìwà náà. (1 Pét. 5:10) Àmọ́ rí i dájú pé o ò ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o pa dà sídìí ìwà burúkú náà, kí Jèhófà lè dáhùn àdúrà ẹ. Yàtọ̀ síyẹn, má ṣe máa ro èròkerò.—Fílí. 4:8; Kól. 3:2. w23.01 10 ¶7, 9-10
Saturday, October 26
Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.—1 Jòh. 4:21.
Ọ̀nà kan tá à ń gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù ni pé à ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Gbogbo ẹni tá a bá rí la máa ń wàásù fún. A kì í sọ pé a ò ní wàásù fún ẹnì kan torí pé orílẹ̀-èdè tó ti wá, ẹ̀yà ẹ̀ àti ipò tó wà láwùjọ yàtọ̀ sí tiwa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń ṣiṣẹ́ fún Jèhófà nìyẹn torí ó fẹ́ “gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) A tún máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. A máa ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún, a sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. A máa ń tù wọ́n nínú tí èèyàn wọn bá kú, a máa ń bẹ̀ wọ́n wò tí wọ́n bá ń ṣàìsàn, a sì tún máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tù wọ́n nínú tí wọ́n bá ní ẹ̀dùn ọkàn. (2 Kọ́r. 1:3-7; 1 Tẹs. 5:11, 14) Gbogbo ìgbà la máa ń gbàdúrà fún wọn torí a mọ̀ pé “ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo lágbára gan-an.”—Jém. 5:16. w23.01 28-29 ¶7-8
Sunday, October 27
Ẹ máa fún ara yín níṣìírí, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró.—1 Tẹs. 5:11.
Bí kọ́lékọ́lé kan bá ṣe ń kọ́lé sí i, bẹ́ẹ̀ lá máa mọṣẹ́ sí i. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń gbé àwọn ará wa ró, àá túbọ̀ máa sunwọ̀n sí i. A lè fún àwọn ará lókun láti fara da ìṣòro tá a bá ń sọ ìrírí àwọn ará wa tó ti fara da ìṣòro fún wọn. (Héb. 11:32-35; 12:1) A lè mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ tá a bá ń sọ ibi táwọn ará wa dáa sí, tá ò sì bá ara wa jà tí èdèkòyédè bá wáyé. (Éfé. 4:3) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yẹ ká tètè máa yanjú aáwọ̀ láàárín ara wa, ká sì máa gbé àwọn ará wa ró. A sì tún lè mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ará lágbára tá a bá ń fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì hàn wọ́n, tá à ń ṣoore fún wọn, tá a sì ń ran àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò lágbára lọ́wọ́. A máa láyọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tá a bá ń ran àwọn ará lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára. Ilé tá a kọ́ lè wó kó sì pa run, àmọ́ ìrànlọ́wọ́ tá a ṣe fáwọn ará wa láti gbé wọn ró máa wà lọ́kàn wọn títí láé! w22.08 22 ¶6; 25 ¶17-18
Monday, October 28
Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fúnni ní ọgbọ́n; ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.—Òwe 2:6.
Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé a nílò ànímọ́ pàtàkì kan tá a bá fẹ́ lóye ohun tá à ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ànímọ́ náà ni ìfòyemọ̀. (Mát. 24:15) Kí ni ìfòyemọ̀? Ìfòyemọ̀ ni kí ẹnì kan rí bí ọ̀rọ̀ kan ṣe tan mọ́ ọ̀rọ̀ míì tàbí bí ọ̀rọ̀ kan ṣe yàtọ̀ sí òmíì, kó sì tún lóye ohun tí ò hàn síta. Bákan náà, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé a nílò ìfòyemọ̀ ká tó lè rí i pé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ń ṣẹ. A tún nílò ànímọ́ yìí ká lè jàǹfààní púpọ̀ látinú gbogbo ohun tá à ń kà nínú Bíbélì. Jèhófà máa ń jẹ́ káwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ní ìfòyemọ̀. Torí náà, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ní ànímọ́ pàtàkì yìí. Àmọ́ kí lo lè ṣe táá fi hàn pé o fẹ́ kí Jèhófà dáhùn àdúrà ẹ? Ronú jinlẹ̀ nípa nǹkan tó o kà, wo bó ṣe tan mọ́ àwọn nǹkan tó o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Gbìyànjú láti lóye àwọn nǹkan tó o kà nínú Bíbélì, kó o sì mọ bó o ṣe lè fi sílò nígbèésí ayé ẹ. (Héb. 5:14) Tó o bá ń fòye mọ ohun tó ò ń kà nínú Bíbélì, á túbọ̀ yé ẹ. w23.02 10 ¶7-8
Tuesday, October 29
Ipasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìyè, tí à ń rìn, tí a sì wà.—Ìṣe 17:28.
Fojú inú wò ó pé ọ̀rẹ́ ẹ fún ẹ ní ilé kan, ilé náà rẹwà, ó ti pẹ́, ó sì níye lórí gan-an. Ọ̀dà tó wà lára ilé náà ti ń ṣí, ilé náà sì ń jò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ibì kan ti bà jẹ́ lára ilé náà, ó níye lórí gan-an, kódà tẹ́nì kan bá máa rà á, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù owó dọ́là ló máa san. Ó dájú pé o máa mọyì ilé náà gan-an, wàá sì tún un ṣe. Lọ́nà kan náà, Jèhófà ti fún wa ní ẹ̀bùn kan tó ṣeyebíye gan-an, ẹ̀bùn náà ni ẹ̀mí wa. Kódà, Jèhófà jẹ́ ká mọ bí ẹ̀mí wa ti ṣe pàtàkì tó lójú ẹ̀ nígbà tó jẹ́ kí Ọmọ ẹ̀ san ìràpadà torí wa. (Jòh. 3:16) Jèhófà ni Orísun ìyè. (Sm. 36:9) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí nígbà tó sọ pé: “Ipasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìyè, tí à ń rìn, tí a sì wà.” (Ìṣe 17:25, 28) Torí náà, a lè sọ pé ẹ̀bùn ni ìwàláàyè jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Gbogbo ohun tá a nílò tó máa jẹ́ ká wà láàyè ni Jèhófà ń pèsè fún wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Ìṣe 14:15-17) Àmọ́ lónìí, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáàbò bò wá lọ́nà ìyanu. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó fẹ́ ni pé ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tọ́jú ara wa, ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun.—2 Kọ́r. 7:1. w23.02 20 ¶1-2
Wednesday, October 30
Kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún ọ sínú ìwé kan.—Jer. 30:2.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run pé ó fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀! Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tí Jèhófà sọ nínú Bíbélì máa ń jẹ́ ká fara da àwọn ìṣòro tá a ní lónìí. Ọlọ́run tún jẹ́ ká mọ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé inú Bíbélì ni Jèhófà ti jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ lára ìwà àti ìṣe ẹ̀. Bá a ṣe ń ronú nípa ìwà àti ìṣe Jèhófà, ó máa ń mórí wa wú gan-an, ó máa ń jẹ́ ká sún mọ́ ọn, ká sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Sm. 25:14) Jèhófà fẹ́ káwa èèyàn mọ òun. Nígbà àtijọ́, ó máa ń lo àlá, ìran àtàwọn áńgẹ́lì láti bá àwa èèyàn sọ̀rọ̀. (Nọ́ń. 12:6; Ìṣe 10:3, 4) Àmọ́ tí wọn ò bá kọ àlá, ìran àti iṣẹ́ táwọn áńgẹ́lì jẹ́ fáwọn èèyàn sínú Bíbélì, báwo la ṣe máa mọ̀ nípa ẹ̀? Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ pé káwọn èèyàn kọ àwọn ohun tó fẹ́ ká mọ̀ “sínú ìwé kan.” Nítorí pé “ọ̀nà Ọlọ́run tòótọ́” pé, ọkàn wa balẹ̀ pé ọ̀nà tó ń gbà bá wa sọ̀rọ̀ ló dáa jù lọ, ó sì ń ṣe wá láǹfààní.—Sm. 18:30. w23.02 2 ¶1-2
Thursday, October 31
Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.—Ìṣe 20:35.
Àwọn nǹkan tó máa mú kó o tẹ̀ síwájú ni kó o máa ṣe. Yan àwọn nǹkan tó máa mú kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára, táá sì mú kó o di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. (Éfé. 3:16) Bí àpẹẹrẹ, o lè mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà ka Bíbélì tó o sì ń gbà kẹ́kọ̀ọ́ túbọ̀ dáa sí i. (Sm. 1:2, 3) O sì lè rí i pé á dáa kó o máa gbàdúrà déédéé, dípò ní ìdákúrekú, kó sì jẹ́ látọkàn wá. Yàtọ̀ síyẹn, á dáa kó o yan eré ìnàjú tó dáa, kó o sì kíyè sí iye àkókò tó ò ń lò nídìí ẹ̀. (Éfé. 5:15, 16) Tó o bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, wàá di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè ran àwọn àgbàlagbà tó wà níjọ ẹ lọ́wọ́ tàbí kó o ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. Ṣé o lè lọ bá wọn ra nǹkan tàbí kó o kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe lo ẹ̀rọ ìgbàlódé wọn? Bákan náà, o lè fìfẹ́ hàn sáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. (Mát. 9:36, 37) Tó bá ṣeé ṣe, pinnu pé iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lo máa ṣe. w22.08 6 ¶16-17