ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es24 ojú ìwé 108-118
  • November

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • November
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Friday, November 1
  • Saturday, November 2
  • Sunday, November 3
  • Monday, November 4
  • Tuesday, November 5
  • Wednesday, November 6
  • Thursday, November 7
  • Friday, November 8
  • Saturday, November 9
  • Sunday, November 10
  • Monday, November 11
  • Tuesday, November 12
  • Wednesday, November 13
  • Thursday, November 14
  • Friday, November 15
  • Saturday, November 16
  • Sunday, November 17
  • Monday, November 18
  • Tuesday, November 19
  • Wednesday, November 20
  • Thursday, November 21
  • Friday, November 22
  • Saturday, November 23
  • Sunday, November 24
  • Monday, November 25
  • Tuesday, November 26
  • Wednesday, November 27
  • Thursday, November 28
  • Friday, November 29
  • Saturday, November 30
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2024
es24 ojú ìwé 108-118

November

Friday, November 1

Kí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ má ṣe ti ẹnu yín jáde, ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró nìkan ni kí ẹ máa sọ.—Éfé. 4:29.

Kò yẹ káwa Kristẹni máa sọ̀sọkúsọ. Àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ èébú kan wà tó tún yẹ ká yẹra fún tó lè dà bíi pé kò fi bẹ́ẹ̀ burú. Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má máa sọ̀rọ̀ tí ò dáa sáwọn èèyàn torí pé àṣà wọn, ẹ̀yà wọn àti ibi tí wọ́n ti wá yàtọ̀ sí tiwa. Yàtọ̀ síyẹn, kò yẹ ká máa sọ̀rọ̀ tó máa bu àwọn ẹlòmíì kù. Máa sọ̀rọ̀ tó ń gbé àwọn èèyàn ró. Dípò ká máa ṣàríwísí àwọn èèyàn, ṣe ló yẹ ká máa gbóríyìn fún wọn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó fi yẹ kí wọ́n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Àmọ́ ṣe ni wọ́n ń kùn ṣáá. Tó bá jẹ́ gbogbo ìgbà la máa ń kùn, ó lè mú káwọn míì náà bẹ̀rẹ̀ sí í kùn. Ṣé ẹ rántí pé ìròyìn tí ò dáa táwọn amí mẹ́wàá yẹn mú wá jẹ́ kí “gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì . . . kùn sí Mósè.” (Nọ́ń. 13:31–14:4) Àmọ́ tá a bá ń sọ̀rọ̀ tó ń gbé àwọn èèyàn ró, ó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀. Torí náà, rí i dájú pé ò ń lo gbogbo àǹfààní tó bá yọ láti gbóríyìn fáwọn ará látọkàn wá. w22.04 8 ¶16-17

Saturday, November 2

Ọwọ́ rẹ ni mo wà látìgbà tí wọ́n ti bí mi; Ìwọ ni Ọlọ́run mi láti inú ìyá mi wá.—Sm. 22:10.

Àtìgbà tí wọ́n ti kọ Bíbélì ni Jèhófà ti ń ran àìmọye ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Jèhófà máa ran àwọn ọmọ ẹ náà lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ ẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́r. 3:​6, 7) Kódà, tí àwọn ọmọ ẹ ò bá fi gbogbo ọkàn wọn sin Jèhófà mọ́, á ṣì máa fìfẹ́ hàn sí wọn. (Sm. 11:4) Tí Jèhófà bá rí i pé ó wù wọ́n láti fi ‘òótọ́ ọkàn’ sin òun, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ìṣe 13:48; 2 Kíró. 16:9) Jèhófà máa jẹ́ kó o sọ ohun tó yẹ fún àwọn ọmọ ẹ ní àkókò tó yẹ kó o sọ ọ́. (Òwe 15:23) Jèhófà tún lè lo arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó nífẹ̀ẹ́ wọn nínú ìjọ láti máa tọ́ wọn sọ́nà. Kódà lẹ́yìn táwọn ọmọ ẹ bá ti dàgbà, Jèhófà lè jẹ́ kí wọ́n rántí àwọn nǹkan tó o ti kọ́ wọn. (Jòh. 14:26) Tó o bá ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ àti àpẹẹrẹ ẹ kọ́ àwọn ọmọ ẹ, Jèhófà máa jẹ́ kó o ṣàṣeyọrí. w22.04 21 ¶18

Sunday, November 3

Dírágónì náà wá bínú gidigidi.—Ìfi. 12:17.

Nítorí pé Sátánì ò lè pa dà sọ́run mọ́, ó ń bínú gidigidi sáwọn ẹni àmì òróró tó kù láyé, ìyẹn àwọn tó ń ṣojú fún Ìjọba Ọlọ́run, “tí iṣẹ́ wọn sì jẹ́ láti jẹ́rìí Jésù.” (2 Kọ́r. 5:20; Éfé. 6:​19, 20) Lọ́dún 1918, wọ́n fẹ̀sùn èké kan mẹ́jọ lára àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó nínú ètò Ọlọ́run, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ. Ṣe ló dà bíi pé wọ́n ti dá iṣẹ́ àwọn ẹni àmì òróró náà dúró tàbí pé wọ́n “pa” wọ́n lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. (Ìfi. 11:​3, 7-11) Àmọ́ ní March 1919, wọ́n dá àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró náà sílẹ̀, nígbà tó sì yá, wọ́n fagi lé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn arákùnrin náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run pa dà. Àmọ́ ìyẹn ò sọ pé kí Sátánì má gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ́. Àtìgbà yẹn ni Sátánì ti ń ṣe inúnibíni tó dà bí “odò” láti fi gbé gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run lọ. (Ìfi. 12:15) Lóòótọ́, “ibi tó ti gba pé [kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa] ní ìfaradà àti ìgbàgbọ́ nìyí.”—Ìfi. 13:10. w22.05 5-6 ¶14-16

Monday, November 4

Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a gbé èdìdì lé, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000).—Ìfi. 7:4.

Nínú ìran kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí àwùjọ méjì tó ń ti àkóso Jèhófà lẹ́yìn, wọ́n sì rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà. Àwùjọ àkọ́kọ́ ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000). Ọlọ́run mú wọn látinú aráyé kí wọ́n lè bá Jésù jọba lọ́run. Àwọn àti Jésù máa ṣàkóso ayé látọ̀run. (Ìfi. 5:​9, 10; 14:​3, 4) Nínú ìran yẹn, Jòhánù rí i pé wọ́n dúró lọ́dọ̀ Jésù lórí Òkè Síónì. (Ìfi. 14:1) Láti ìgbà ayé àwọn àpọ́sítélì ni Ọlọ́run ti ń yan ọ̀pọ̀ lára àwọn tó máa jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. (Lúùkù 12:32; Róòmù 8:17) Àmọ́ Jòhánù sọ pé díẹ̀ lára wọn ló máa ṣẹ́ kù láyé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. (Ìfi. 12:17) Lẹ́yìn náà, Jèhófà máa kó àwọn tó ṣẹ́ kù náà lọ sọ́run nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá ń lọ lọ́wọ́. Wọ́n máa dara pọ̀ mọ́ àwọn tó kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ títí wọ́n fi kú, tí wọ́n sì ti wà lọ́run. Gbogbo wọn máa bá Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run.—Mát. 24:31; Ìfi. 5:​9, 10. w22.05 16 ¶4-5

Tuesday, November 5

Fetí sí àwọn àṣẹ mi!—Àìsá. 48:18.

Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa fojú tó tọ́ wo ara wọn. Ó fi dá wọn lójú pé: “Gbogbo irun orí yín la ti kà.” (Mát. 10:30) Ọ̀rọ̀ yẹn fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an pàápàá tá a bá ń rò pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Ìyẹn fi hàn pé Bàbá wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, a sì níyì lójú ẹ̀. Tí Jèhófà bá kà wá yẹ láti máa jọ́sìn ẹ̀ àti láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun, kò yẹ ká rò pé ohun tí Jèhófà ṣe ò tọ́. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sẹ́yìn, Ilé Ìṣọ́ kan sọ irú ojú tó yẹ ká máa fi wo ara wa, ó ní: “Dájúdájú, a ò ní fẹ́ ro ara wa ju bó ti yẹ lọ débi tá a máa fi di agbéraga. Bẹ́ẹ̀ la ò tún ní rora wa pin pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa wo ara wa bá a ṣe rí gan-an, ká mọ ibi tágbára wa dé ká sì mọ̀wọ̀n ara wa.” w22.05 24-25 ¶14-16

Wednesday, November 6

Mo tún ń gbàdúrà . . . kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan.—Jòh. 17:​20, 21.

Kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ṣe kí ìjọ lè túbọ̀ wà níṣọ̀kan? Ó yẹ ká jẹ́ ẹni àlàáfíà. (Mát. 5:9; Róòmù 12:18) Gbogbo ìgbà tá a bá ń ṣe ohun táá mú kí àlàáfíà wà láàárín àwa àtàwọn ará inú ìjọ là ń mú kí Párádísè tẹ̀mí wa dáa sí i. Ká máa rántí pé Jèhófà ló pe gbogbo àwọn tó wà nínú Párádísè tẹ̀mí láti wá máa ṣe ìjọsìn mímọ́. (Jòh. 6:44) Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó tó bá rí i tá à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn ẹ̀ lè máa pọ̀ sí i! (Àìsá. 26:3; Hág. 2:7) Jèhófà máa ń ṣe nǹkan rere fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, àmọ́ báwo la ṣe lè jàǹfààní àwọn nǹkan rere yìí? Bá a ṣe lè ṣe é ni pé ká máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan tá a ti kọ́ nínú Bíbélì. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kọ́, ó máa jẹ́ ká láwọn ìwà tó yẹ Kristẹni, ó sì máa jẹ́ ká ní “ìfẹ́ ará” àti “ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara [wa]” nínú ìjọ.—Róòmù 12:10. w22.11 12-13 ¶16-18

Thursday, November 7

Màá dárí àṣìṣe wọn jì wọ́n, mi ò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.—Jer. 31:34.

Tá a bá gbà pé lóòótọ́ ni Jèhófà ti dárí jì wá, a máa gbádùn “àwọn àsìkò ìtura,” ọkàn wa á balẹ̀, àá sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Kò sẹ́ni tó lè dárí jì wá lọ́nà bẹ́ẹ̀ àfi “Jèhófà fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 3:19) Tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ó máa ń jẹ́ ká pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀ bíi pé a ò tiẹ̀ ṣẹ̀ ẹ́ rárá. Tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, kò ní fẹ̀sùn yẹn kàn wá mọ́ tàbí kó tún fìyà ẹ̀ jẹ wá. (Àìsá. 43:25) “Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn,” bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà máa ń jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí òun. (Sm. 103:12) Tá a bá ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jì wá pátápátá, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ ká sì máa bọ̀wọ̀ fún un. (Sm. 130:4) Kì í ṣe bí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan dá ṣe burú tó tàbí bó ṣe kéré tó ni Jèhófà máa ń wò tó bá fẹ́ dárí ji ẹni náà. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà mọ̀ nípa wa torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, òun ni Afúnnilófin wa, òun sì ni Onídàájọ́ wa. Torí náà, àwọn nǹkan tí Jèhófà mọ̀ yìí ló máa ń lò tó bá fẹ́ pinnu bóyá kóun dárí ji ẹnì kan tàbí kóun má dárí jì í. w22.06 5 ¶12-14

Friday, November 8

Ẹnikẹ́ni tó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà àti pé òun ló ń san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.—Héb. 11:6.

Jèhófà sọ pé lọ́jọ́ iwájú, òun máa ṣe ohun rere fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ òun. Láìpẹ́, Jèhófà máa mú àìsàn, ìbànújẹ́ àti ikú kúrò. (Ìfi. 21:​3, 4) Ó máa ran “àwọn oníwà pẹ̀lẹ́” tó gbẹ́kẹ̀ lé e lọ́wọ́ láti sọ ayé di Párádísè. (Sm. 37:​9-11) Ó tún máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ju ohun tá à ń gbádùn báyìí lọ. Ẹ ò rí i pé ohun tó dáa ni Jèhófà fẹ́ fún wa! Àmọ́ kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ? Ìdí ni pé Jèhófà kì í sọ̀rọ̀ kó má ṣẹ. Torí náà, ó yẹ ká “gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” (Sm. 27:14) Tá a bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ la gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó yẹ ká mú sùúrù, kí inú wa sì máa dùn pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ láìpẹ́. (Àìsá. 55:​10, 11) Ẹ jẹ́ káwa náà jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kó sì dá wa lójú pé ó máa san èrè “fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.” w22.06 20 ¶1; 25 ¶18

Saturday, November 9

Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ nílò, kódà kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.—Mát. 6:8.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà tó jẹ́ Olórí ìdílé wa máa ṣe ohun tó wà nínú 1 Tímótì 5:8. Tá a bá gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa àti ìdílé wa, kò ní ṣòro fún wa láti gbà pé ó máa pèsè àwọn ohun tá a nílò. (Mát. 6:​31-33) Ó máa ń wu Jèhófà gan-an láti pèsè àwọn ohun tá a nílò, ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì lawọ́ sí wa gan-an. Nígbà tó dá ayé, kì í ṣe àwọn nǹkan tó máa gbé ẹ̀mí wa ró nìkan ló pèsè. Ó tún fìfẹ́ pèsè àwọn nǹkan míì táá jẹ́ kára tù wá, ká sì gbádùn ara wa. (Jẹ́n. 2:9) Torí náà, tá ò bá lóhun tó pọ̀ tó, ẹ jẹ́ ká máa dúpẹ́ pé Jèhófà ṣì ń pèsè ohun tá a nílò fún wa. (Mát. 6:11) Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé kò sí nǹkan tara tá a lè yááfì báyìí tá a lè fi wé àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè fún wa àti èyí tó máa pèsè fún wa lọ́jọ́ iwájú.—Àìsá. 65:​21, 22. w22.06 15 ¶7-8

Sunday, November 10

Àwọn tó dàgbà ni oúnjẹ líle wà fún.—Héb. 5:14.

Kì í ṣe àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan ló yẹ kó máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀. Gbogbo wa ló yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé tá a bá ń tẹ̀ lé nǹkan tá à ń kọ́ nínú Bíbélì, á jẹ́ ká lè “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” Ó ṣòro gan-an lákòókò tá a wà yìí láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà torí ìwà ìbàjẹ́ pọ̀ gan-an láyé. Àmọ́ Jésù ń rí i dájú pé à ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára. Inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lá sì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn nǹkan yìí. Bíi ti Jésù, àwa náà ti jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run. (Jòh. 17:​6, 26) Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1931, a bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì ń fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Bàbá wa ọ̀run. (Àìsá. 43:​10-12) Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí gbogbo ibi tó yẹ kó wà. w22.07 11 ¶11-12

Monday, November 11

Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ fún ọ̀nà mi.—Sm. 119:105.

Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run wà lára ẹ̀kọ́ òtítọ́. Jésù fi òtítọ́ yìí wé ìṣúra kan tá a fi pa mọ́. Nínú Mátíù 13:​44, Jésù sọ pé: “Ìjọba ọ̀run dà bí ìṣúra tí a fi pa mọ́ sínú pápá, èyí tí ọkùnrin kan rí, tó sì fi pa mọ́; torí pé inú rẹ̀ ń dùn, ó lọ ta gbogbo ohun tó ní, ó sì ra pápá yẹn.” Ṣé ẹ kíyè sí i pé ọkùnrin náà ò wá ìṣúra náà kiri? Àmọ́ nígbà tó rí i, ó yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kó lè rà á. Kódà, ó ta gbogbo ohun tó ní. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó mọ bí ìṣúra náà ṣe ṣeyebíye tó. A mọ̀ pé kò sí ohun tí ayé yìí lè fún wa tó lè dà bí ayọ̀ tá à ń rí bá a ṣe ń sin Jèhófà àti ìrètí tá a ní pé a máa rí ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú nínú Ìjọba Ọlọ́run. Kò sí ohunkóhun tá a lè yááfì báyìí tó ṣeyebíye tó àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà. Bá a ṣe ń “ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún” lohun tó ń fún wa láyọ̀ jù lọ.—Kól. 1:10. w22.08 15 ¶8-9; 17 ¶12

Tuesday, November 12

Ṣé ó wá yẹ kí n hùwà burúkú tó tó báyìí, kí n sì ṣẹ Ọlọ́run?—Jẹ́n. 39:9.

Báwo ni Jósẹ́fù ṣe mọ̀ pé ‘ìwà burúkú’ ni àgbèrè lójú Ọlọ́run? Ó ṣe tán, ọgọ́rùn-ún méjì (200) ọdún lẹ́yìn tí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù ni Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin tó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.” (Ẹ́kís. 20:14) Síbẹ̀, Jósẹ́fù mọ̀ pé Jèhófà ò fẹ́ ká ṣàgbèrè, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì mọ Òfin yìí nígbà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, Jósẹ́fù mọ̀ pé Jèhófà ṣètò ìgbéyàwó láàárín ọkùnrin kan àti obìnrin kan. Ó sì ṣeé ṣe kó ti gbọ́ nípa bí Jèhófà ṣe gba Sérà ìyá bàba bàbá ẹ̀ sílẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nígbà tí wọ́n fẹ́ bá a ṣàgbèrè. (Jẹ́n. 2:24; 12:​14-20; 20:​2-7) Bí Jósẹ́fù ṣe ń ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, ó mọ ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ lójú Ọlọ́run. Torí pé Jósẹ́fù nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà òdodo rẹ̀, ó pinnu pé ohun tó tọ́ lòun máa ṣe. w22.08 26 ¶1-2

Wednesday, November 13

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ máa jí, àwọn kan sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Dán. 12:2.

Àlàyé tá a ṣe nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ ni pé àjíǹde ìṣàpẹẹrẹ tàbí bí àwa èèyàn Ọlọ́run ṣe rí okun gbà pa dà láti máa jọ́sìn Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ló ń sọ nípa ẹ̀. Àmọ́, ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ kọ́ nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àjíǹde tó máa wáyé nínú ayé tuntun ló ń sọ nípa ẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọ́n tún lo ọ̀rọ̀ náà “iyẹ̀pẹ̀” ìyẹn erùpẹ̀ nínú Jóòbù 17:​16, ohun kan náà lòun àti “Isà Òkú” sì jẹ́. Èyí fi hàn pé àjíǹde tí Dáníẹ́lì 12:2 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ máa wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn bá ti dópin àti lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì. Kí ni Dáníẹ́lì 12:2 ń sọ nígbà tó ní wọ́n máa jí àwọn èèyàn kan dìde sí “ìyè àìnípẹ̀kun”? Ohun tó ń sọ ni pé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àwọn tí wọ́n jí dìde, tí wọ́n ti mọ Jèhófà, tí wọ́n sì ti pinnu pé àwọn á máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà nìṣó àti pé àwọn á máa gbọ́ràn sí òun àti Jésù lẹ́nu ló máa gba ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 17:3. w22.09 21 ¶6-7

Thursday, November 14

[Ìfẹ́] máa ń gba ohun gbogbo gbọ́.—1 Kọ́r. 13:7.

Jèhófà ò fẹ́ ká fọkàn tán àwọn ará láìnídìí, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fẹ́ ká fọkàn tán wọn torí àwọn fúnra wọn ti fi hàn pé àwọn ṣeé fọkàn tán. Bó ṣe jẹ́ pé ìwà wa ló ń jẹ́ káwọn èèyàn máa bọ̀wọ̀ fún wa, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé ìwà wa ló máa jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa, ó sì lè gba àkókò díẹ̀ kíyẹn tó ṣẹlẹ̀. Kí ló máa jẹ́ kó o fọkàn tán àwọn ará? Sún mọ́ wọn kó o lè mọ̀ wọ́n dáadáa. Máa bá wọn sọ̀rọ̀ nípàdé. Ẹ jọ máa lọ sóde ìwàásù. Máa mú sùúrù fún wọn, kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn ṣeé fọkàn tán. Níbẹ̀rẹ̀, kò pọn dandan kó o sọ gbogbo nǹkan nípa ara ẹ fún ẹni tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀. Bí ẹ bá ṣe ń di ọ̀rẹ́ ara yín sí i, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn nǹkan míì nípa ara ẹ fún un. (Lúùkù 16:10) Àmọ́, kí lo máa ṣe tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣe nǹkan tó fi hàn pé òun ò ṣeé fọkàn tán? Má sọ pé o ò ní bá a ṣọ̀rẹ́ mọ́, ṣe ni kó o jẹ́ kí atẹ́gùn fẹ́ sí ọ̀rọ̀ náà kó o tó ṣèpinnu. Yàtọ̀ síyẹn, má jẹ́ kí nǹkan táwọn èèyàn mélòó kan ṣe sí ẹ mú kó o sọ pé o ò ní fọkàn tán àwọn ará mọ́. w22.09 4 ¶7-8

Friday, November 15

Ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé.—2 Kíró. 16:9.

Alàgbà kan tó ń jẹ́ Miqueas rántí ìgbà kan tó ronú pé àwọn alàgbà ṣe ohun tí ò dáa sóun. Síbẹ̀, Miqueas ronú lọ́nà tó tọ́, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó má bàa ṣinú bí. Ó gbàdúrà léraléra, ó sì bẹ Jèhófà pé kó fún òun ní ẹ̀mí mímọ́ àti okun láti fara da ìṣòro náà. Ó tún ṣèwádìí nínú àwọn ìwé wa kó lè rí ìsọfúnni tó máa ràn án lọ́wọ́. Kí la rí kọ́? Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣe ohun tí ò dáa sí ẹ, fara balẹ̀, má ṣinú bí, má sì di ẹni náà sínú. O lè má mọ ohun tó mú kí ẹni náà sọ̀rọ̀ lọ́nà yẹn tàbí hùwà lọ́nà yẹn. Torí náà, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ohun tó mú kó hu irú ìwà yẹn. Gbà pé ẹni náà ò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe nǹkan tó ṣe sí ẹ, sì gbìyànjú láti dárí jì í. (Òwe 19:11) Rántí pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ, á sì fún ẹ lókun láti fara dà á.—Oníw. 5:8. w22.11 21 ¶5

Saturday, November 16

Mo máa ń yẹra fún àwọn tó ń fi ẹni tí wọ́n jẹ́ pa mọ́.—Sm. 26:4.

Yan àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àwọn ọ̀rẹ́ tó o bá yàn ló máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá wàá di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. (Òwe 13:20) Julien tó ti wá di alàgbà báyìí sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, mo ní àwọn ọ̀rẹ́ tá a jọ máa ń lọ wàásù. Wọ́n nítara, wọ́n sì jẹ́ kí n rí i pé iṣẹ́ aláyọ̀ niṣẹ́ ìwàásù. Mo tún rí i pé ìdí tí mi ò fi láwọn ọ̀rẹ́ gidi tẹ́lẹ̀ ni pé àwọn ojúgbà mi nìkan ni mo yàn lọ́rẹ̀ẹ́.” Kí lo máa ṣe tó o bá rí i pé ẹni tó ò ń bá kẹ́gbẹ́ nínú ìjọ lè ba ìwà ẹ jẹ́? Pọ́ọ̀lù mọ àwọn kan nínú ìjọ nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọn kì í hùwà bíi Kristẹni, torí náà ó sọ fún Tímótì pé kó yẹra fún wọn. (2 Tím. 2:​20-22) A ti ṣiṣẹ́ kára ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Torí náà, kò yẹ ká jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ba àjọṣe wa pẹ̀lú Bàbá wa ọ̀run jẹ́. w22.08 5-6 ¶13-15

Sunday, November 17

Jìnnà sí òmùgọ̀ èèyàn.—Òwe 14:7.

Àwa Kristẹni tòótọ́ kì í hùwà bí àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ la máa ń ṣe, a sì máa ń pa àwọn òfin ẹ̀ mọ́. A lè mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run túbọ̀ lágbára tá a bá ń ronú nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run àtàwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. O lè kíyè sí ohun táwọn òmùgọ̀ tó kọ ọgbọ́n Jèhófà máa ń fọwọ́ ara wọn fà sórí ara wọn, kó o wá fi wé bí ìgbésí ayé ẹ ṣe dáa torí pé ò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. (Sm. 32:​8, 10) Gbogbo èèyàn ni Jèhófà fẹ́ kó jàǹfààní ọgbọ́n òun, àmọ́ kò fipá mú ẹnikẹ́ni nínú wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ó sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí ò bá fetí sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n. (Òwe 1:​29-32) Àwọn tí ò ṣègbọràn sí Jèhófà máa “jìyà ọ̀nà tí wọ́n yàn.” Tó bá yá, ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé á kó ìdààmú àti ìyọnu bá wọn, níkẹyìn wọ́n á pa run. Àmọ́ Jèhófà ṣèlérí fáwọn tó ń fetí sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó fún wa, tí wọ́n sì ń ṣe ohun tó fẹ́ pé: “Ẹni tó ń fetí sí mi á máa gbé lábẹ́ ààbò, ìbẹ̀rù àjálù kò sì ní yọ ọ́ lẹ́nu.”—Òwe 1:33. w22.10 21 ¶11-13

Monday, November 18

Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tó bẹ̀rù Jèhófà, tó ń rìn ní àwọn ọ̀nà Rẹ̀.—Sm. 128:1.

Tẹ́nì kan bá bẹ̀rù Jèhófà, ẹni náà á máa bọ̀wọ̀ fún un, kò sì ní ṣe ohun tó máa bà á nínú jẹ́. (Òwe 16:6) Torí náà, ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run tó bá dọ̀rọ̀ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ tí Bíbélì sọ. (2 Kọ́r. 7:1) A máa láyọ̀ tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, tá a sì kórìíra ohun tó kórìíra. (Sm. 37:27; 97:10; Róòmù 12:9) Ẹnì kan lè mọ̀ pé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti fún wa ní ìlànà nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, àmọ́ ẹni náà tún gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. (Róòmù 12:2) Ìwà tá a bá ń hù ló máa fi hàn pé a gbà lóòótọ́ pé àwọn ìlànà Jèhófà máa ṣe wá láǹfààní. (Òwe 12:28) Èrò tí Dáfídì náà ní nìyẹn torí ó sọ nípa Jèhófà pé: “O jẹ́ kí n mọ ọ̀nà ìyè. Ayọ̀ púpọ̀ wà ní iwájú rẹ, ìdùnnú sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ títí láé.”—Sm. 16:11. w22.10 8 ¶9-10

Tuesday, November 19

Ọmọ ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara rẹ̀, àfi ohun tó bá rí tí Baba ń ṣe nìkan.—Jòh. 5:19.

Jésù fi ojú tó tọ́ wo ara ẹ̀, kò sì gbéra ga rárá. Kó tó wá sáyé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti bá Jèhófà ṣe lọ́run. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé nípasẹ̀ Jésù “ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé.” (Kól. 1:16) Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó rántí àwọn nǹkan tó ṣe nígbà tó wà lọ́dọ̀ Bàbá ẹ̀ lọ́run. (Mát. 3:16; Jòh. 17:5) Síbẹ̀, àwọn nǹkan tó rántí yẹn ò mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, kó sì ronú pé òun dáa ju gbogbo àwọn èèyàn yòókù lọ. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé òun wá kì í ṣe torí ‘ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún òun, àmọ́ kóun lè ṣe ìránṣẹ́, kóun sì fi ẹ̀mí òun ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.’ (Mát. 20:28) Kódà, ó sọ pé òun ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara òun. Ẹ ò rí i pé Jésù nírẹ̀lẹ̀ gan-an! Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ fún gbogbo wa. w22.05 24 ¶13

Wednesday, November 20

Pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.—Àìsá. 55:7.

Tí Jèhófà bá fẹ́ dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan, Jèhófà máa wò ó bóyá ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà mọ̀ pé ohun tóun ṣe ò dáa. Jésù jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú ohun tó sọ nínú Lúùkù 12:​47, 48. Tí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣe nǹkan tí ò dáa tàbí nǹkan tó burú, tó sì mọ̀ pé inú Jèhófà ò dùn sí nǹkan náà, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ló dá yẹn. Tẹ́nì kan bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà lè má dárí jì í. (Máàkù 3:29; Jòh. 9:41) Àmọ́, ṣé Jèhófà máa dárí jì wá tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni! Jèhófà tún máa ń wò ó bóyá ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Ìrònúpìwàdà túmọ̀ sí kéèyàn “yí èrò ẹ̀, ìwà ẹ̀ àti ohun tó fẹ́ ṣe pa dà.” Ara ohun tó yẹ kó ṣe ni pé kó kábàámọ̀ tàbí kó banú jẹ́ nítorí àwọn nǹkan tí ò dáa tó ti ṣe tàbí torí pé ó mọ àwọn nǹkan tó yẹ kó ṣe àmọ́ tí ò ṣe é. Tẹ́nì kan bá ronú pìwà dà, kì í ṣe àwọn nǹkan tí ò dáa tó ṣe nìkan ló máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a. Ó tún máa ń banú jẹ́ torí pé kò fọwọ́ gidi mú àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn ló sì kó o síṣòro. w22.06 5-6 ¶15-17

Thursday, November 21

Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.—2 Tím. 3:12.

Àwọn ọ̀tá wa máa ń parọ́ mọ́ àwọn tó ń ṣàbójútó nínú ètò Ọlọ́run, ká má bàa fọkàn tán wọn mọ́. (Sm. 31:13) Wọ́n ti fàṣẹ ọba mú àwọn arákùnrin wa kan, wọ́n sì fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n. Irú ohun kan náà ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fàṣẹ ọba mú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì fẹ̀sùn èké kàn án. Àwọn kan pa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tì nígbà tó wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù. (2 Tím. 1:​8, 15; 2:​8, 9) Ẹ fojú inú wo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe máa rí lára Pọ́ọ̀lù. Ó ti fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro, kódà ó ti fi ẹ̀mí ẹ̀ wewu nítorí wọn. (Ìṣe 20:​18-21; 2 Kọ́r. 1:8) Torí náà, ẹ má jẹ́ ká dà bí àwọn tó pa Pọ́ọ̀lù tì! Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé àwọn tó ń ṣàbójútó wa ni Sátánì máa ń kọ́kọ́ gbéjà kò. Ohun tó fẹ́ ni pé káwọn tó ń ṣàbójútó wa má jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà mọ́, kíyẹn sì mú kẹ́rù bà wá. (1 Pét. 5:8) Torí náà, túbọ̀ máa ran àwọn tó ń ṣàbójútó wa lọ́wọ́, kó o sì dúró tì wọ́n nígbà ìṣòro.—2 Tím. 1:​16-18. w22.11 16-17 ¶8-11

Friday, November 22

Ṣé o ò bẹ̀rù Ọlọ́run rárá ni?—Lúùkù 23:40.

Ó ṣeé ṣe kí ọ̀daràn tó ronú pìwà dà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù nígbà tí wọ́n kàn án mọ́gi yẹn jẹ́ Júù. Ọlọ́run kan ṣoṣo làwọn Júù ń sìn, àmọ́ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ń sin ọ̀pọ̀ ọlọ́run. (Ẹ́kís. 20:​2, 3; 1 Kọ́r. 8:​5, 6) Tó bá jẹ́ pé ọ̀daràn yẹn kì í ṣe Júù ni, ìbéèrè tí ì bá wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní ni, “Ṣé o ò bẹ̀rù àwọn ọlọ́run rárá ni?” Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run ò rán Jésù sáwọn èèyàn orílẹ̀-èdè, “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù” ló rán an sí. (Mát. 15:24) Ọlọ́run ti sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé òun máa jí àwọn òkú dìde, ó sì ṣeé ṣe kí ọ̀daràn tó ronú pìwà dà náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ohun tó sọ fi hàn pé ó gbà pé Jèhófà máa jí Jésù dìde láti ṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. Ó hàn gbangba pé ọkùnrin náà nírètí pé Ọlọ́run máa jí òun dìde. Tó bá jẹ́ pé Júù ni ọ̀daràn tó ronú pìwà dà náà, ó ṣeé ṣe kó mọ̀ nípa Ádámù àti Éfà. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó mọ̀ pé ọgbà kan tó rẹwà, tó sì wà láyé ni Párádísè tí Jésù ń sọ nínú Lúùkù 23:43.—Jẹ́n. 2:15. w22.12 8-9 ¶2-3

Saturday, November 23

Gbogbo wọn tẹra mọ́ àdúrà pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan.—Ìṣe 1:14.

Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń jẹ́ ká lè máa ṣiṣẹ́ ìwàásù. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Sátánì ń gbógun tì wá kó lè dá iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe dúró. (Ìfi. 12:17) Tá a bá fojú èèyàn wò ó, a ò lè borí Sátánì. Àmọ́ bá a ṣe ń wàásù nìṣó, ṣe là ń ṣẹ́gun Sátánì! (Ìfi. 12:​9-11) Lọ́nà wo? Tá a bá ń wàásù, ṣe là ń fi hàn pé ẹ̀rù Sátánì ò bà wá bó ṣe ń halẹ̀ mọ́ wa. Gbogbo ìgbà tá a bá ń wàásù, ṣe là ń ṣẹ́gun Sátánì. Torí náà, a lè sọ pé ohun tó ń ràn wá lọ́wọ́ ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run àti bá a ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa. (Mát. 5:​10-12; 1 Pét. 4:14) Ó dá wa lójú pé ẹ̀mí Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro èyíkéyìí tá a bá bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (2 Kọ́r. 4:​7-9) Torí náà, kí la lè ṣe kí Ọlọ́run lè máa fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀? Gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀, kó sì dá wa lójú pé ó máa gbọ́ àdúrà wa. w22.11 5 ¶10-11

Sunday, November 24

Ẹ̀yin ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa kìlọ̀ fún àwọn tó ń ṣe ségesège, ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́, ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo èèyàn.—1 Tẹs. 5:14.

A máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú wọn. Táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá, a máa ń dárí jì wọ́n bíi ti Jèhófà. Tí Jèhófà bá lè yọ̀ǹda Ọmọ ẹ̀ kó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, ṣé kò wá yẹ káwa náà dárí ji àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá? A ò ní fẹ́ dà bí ẹrú burúkú tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú ọ̀kan lára àkàwé rẹ̀. Lẹ́yìn tí ọ̀gá rẹ̀ fagi lé gbèsè ńlá tó jẹ, ẹrú yẹn kọ̀ láti dárí ji ẹrú míì tó jẹ ẹ́ ní gbèsè tí ò tó nǹkan. (Mát. 18:​23-35) Torí náà, tí èdèkòyédè bá wà láàárín ìwọ àti ẹnì kan nínú ìjọ, ṣé o lè kọ́kọ́ lọ yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ẹni yẹn, kí àlàáfíà lè wà kó o tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi? (Mát. 5:​23, 24) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù gan-an. w23.01 29 ¶8-9

Monday, November 25

Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan.—Òwe 19:17.

Ọ̀nà kan tó o lè gbà mọ ohun táwọn ará fẹ́ ni pé kó o fọgbọ́n bi wọ́n láwọn ìbéèrè táá jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 20:5) O lè bi wọ́n pé ṣé ẹ ní oúnjẹ, oògùn àtàwọn nǹkan míì tẹ́ ẹ nílò? Ṣé wọn ò máa dín àwọn òṣìṣẹ́ kù níbi iṣẹ́ yín, ṣé ẹ ṣì ń rówó ilé san? O tún lè bi wọ́n pé ṣé wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n lè rí nǹkan tí ìjọba ṣètò fáwọn aráàlú gbà? Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé ká máa fún ara wa níṣìírí, ká sì máa ran ara wa lọ́wọ́. (Gál. 6:10) Kódà tó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú díẹ̀ la sọ fún ẹnì kan tó ń ṣàìsàn, ó lè mú kára ẹ̀ yá gágá. Ọmọ kékeré kan lè fi káàdì tàbí àwòrán tó yà ránṣẹ́ sí arákùnrin kan láti fún un níṣìírí. Ọ̀dọ́ kan lè lọ bá arábìnrin kan jíṣẹ́ tàbí kó lọ bá a ra nǹkan lọ́jà. Àbí ṣé a lè se oúnjẹ fún ẹnì kan tí ara ẹ̀ ò yá? Àwọn ará kan ti fi lẹ́tà ìdúpẹ́ ránṣẹ́ sáwọn alàgbà tí wọ́n ṣiṣẹ́ kára lákòókò àjàkálẹ̀ àrùn. Ẹ ò rí i pé ó máa dáa gan-an tá a bá ń ‘fún ara wa níṣìírí, tí a sì ń gbé ara wa ró!’—1 Tẹs. 5:11. w22.12 22 ¶2; 23 ¶5-6

Tuesday, November 26

Ẹ mà ṣàṣìṣe o.—Máàkù 12:27.

Àwọn Sadusí mọ ohun tó wà nínú ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù dáadáa, àmọ́ wọn ò gba àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú ẹ̀ gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ohun tí Jésù sọ nígbà táwọn Sadusí ta kò ó lórí ọ̀rọ̀ àjíǹde. Jésù bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ ò tíì kà á nínú ìwé Mósè ni, nínú ìtàn igi ẹlẹ́gùn-ún, pé Ọlọ́run sọ fún un pé: ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’?” (Máàkù 12:​18, 26) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn Sadusí ti ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn, ìbéèrè tí Jésù bi wọ́n fi hàn pé wọn ò gba ẹ̀kọ́ pàtàkì kan gbọ́, ìyẹn ẹ̀kọ́ àjíǹde. (Lúùkù 20:38) Kí lo kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Gbogbo ẹ̀kọ́ tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì kan tàbí ìtàn Bíbélì tá a kà ló yẹ ká kíyè sí. Kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tá a ti mọ̀ nìkan ló yẹ ká máa kíyè sí, ó tún yẹ ká máa kíyè sí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ àtàwọn ìlànà tó fara sin nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a kà. w23.02 11 ¶9-10

Wednesday, November 27

A ní àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tó pọ̀ gan-an yí wa ká.—Héb. 12:1.

Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní ló dojú kọ àdánwò tó le gan-an, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ olóòótọ́ títí dópin. (Héb. 11:​36-40) Ṣé bí wọ́n ṣe fara dà á àti ohun tí wọ́n ṣe fún Jèhófà já sásán? Rárá o! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìlérí Ọlọ́run ló ṣẹ lójú wọn, wọn ò sọ̀rètí nù nínú Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, torí wọ́n mọ̀ pé inú Jèhófà dùn sí wọn, ó dá wọn lójú pé àwọn máa rí àwọn ìlérí Jèhófà nígbà tó bá ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. (Héb. 11:​4, 5) Àpẹẹrẹ wọn lè mú káwa náà túbọ̀ pinnu pé a ò ní sọ̀rètí nù láé. Nǹkan túbọ̀ ń burú sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nínú ayé tá à ń gbé yìí. (2 Tím. 3:13) Sátánì ò sì tíì ṣíwọ́ láti máa dán àwa ìránṣẹ́ Jèhófà wò. Ìṣòro yòówù kó dé bá wa lọ́jọ́ iwájú, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa lo gbogbo okun wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, torí a mọ̀ pé “a ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè.”—1 Tím. 4:10. w22.06 25 ¶17-18

Thursday, November 28

Èrè wo ló wà nínú ikú mi . . . ? Ṣé erùpẹ̀ lè yìn ọ́?—Sm. 30:9.

Ọ̀kan lára ìdí tó fi yẹ ká máa tọ́jú ara wa ni pé, á jẹ́ ká sin Jèhófà débi tágbára wa gbé e dé. (Máàkù 12:30) Torí náà, a kì í ṣe ohun táá mú ká máa ṣàìsàn. (Róòmù 12:1) Lóòótọ́, kò sí bá a ṣe lè tọ́jú ara wa tó, a ṣì máa ń ṣàìsàn. Àmọ́, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí Jèhófà lè mọ̀ pé a mọyì ìwàláàyè tó fún wa. Tá a bá ti darúgbó tàbí tá à ń ṣàìsàn, ó lè má jẹ́ ká ṣe gbogbo nǹkan tá a ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ìyẹn lè jẹ́ ká banú jẹ́ kí nǹkan sì tojú sú wa. Síbẹ̀, kò yẹ ká jẹ́ kí nǹkan tojú sú wa débi pé a ò ní tọ́jú ara wa mọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò sí bá a ṣe dàgbà tó tàbí bí àìsàn wa ṣe le tó, a ṣì lè máa yin Jèhófà bíi ti Ọba Dáfídì. Inú wa mà dùn o pé a ṣeyebíye gan-an lójú Ọlọ́run bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá! (Mát. 10:​29-31) A mọ̀ pé tá a bá tiẹ̀ kú, ó máa jí wa dìde. (Jóòbù 14:​14, 15) Torí náà, ní báyìí tá a ṣì wà láàyè, ó yẹ ká máa dáàbò bo ara wa, ká sì máa tọ́jú ara wa ká lè ní ìlera tó dáa. w23.02 20-21 ¶3-5

Friday, November 29

Ẹnikẹ́ni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, kò lè ní ìdáríjì kankan títí láé.—Máàkù 3:29.

Ṣé orúkọ àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó jẹ́ ara àgùntàn mìíràn ṣì máa wà nínú ìwé ìyè lẹ́yìn tí wọ́n bá la Amágẹ́dọ́nì já? Bẹ́ẹ̀ ni. (Ìfi. 7:14) Jésù sọ pé àwọn tó fìwà jọ àgùntàn máa lọ “sínú ìyè àìnípẹ̀kun.” (Mát. 25:46) Àmọ́ kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà máa fún àwọn tó bá la Amágẹ́dọ́nì já ní ìyè àìnípẹ̀kun. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, ó “máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, ó sì máa darí wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè.” Àwọn tó bá ṣègbọràn sí Kristi, tí Jèhófà sì rí i pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ni orúkọ wọn máa wà nínú ìwé ìyè náà títí láé. (Ìfi. 7:​16, 17) Bákan náà, Jèhófà máa pa àwọn ewúrẹ́ run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Jésù sọ pé wọ́n “máa lọ sínú ìparun àìnípẹ̀kun.” (Mát. 25:46) Ẹ̀mí Ọlọ́run darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé, “àwọn yìí máa fara gbá ìyà ìdájọ́ ìparun ayérayé.”—2 Tẹs. 1:9; 2 Pét. 2:9. w22.09 16 ¶7-8

Saturday, November 30

Ohun gbogbo ni àkókò wà fún. —Oníw. 3:1.

Tẹ́yin ìdílé bá ń lo ohun tí Jèhófà dá láti gbádùn ara yín lásìkò ìsinmi, á jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín. Jèhófà ti pèsè ọ̀pọ̀ ibi tó rẹwà gan-an tá a ti lè lọ gbádùn ara wa. Ọ̀pọ̀ ìdílé gbádùn kí wọ́n jọ máa lọ sí ọgbà ìgbafẹ́, ìgbèríko, orí òkè àti etíkun. Nínú ayé tuntun, ẹ̀yin òbí àtàwọn ọmọ yín máa gbádùn àwọn nǹkan tí Jèhófà dá gan-an ju bí ẹ ṣe ń gbádùn ẹ̀ báyìí lọ. Tó bá dìgbà yẹn, a ò ní máa bẹ̀rù àwọn ẹranko mọ́; àwọn náà ò sì ní bẹ̀rù wa mọ́. (Àìsá. 11:​6-9) Yàtọ̀ síyẹn, títí ayé làá máa gbádùn àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. (Sm. 22:26) Àmọ́ o, kò yẹ kẹ́yin òbí dúró dìgbà yẹn kẹ́ ẹ tó ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbádùn àwọn nǹkan yẹn. Torí náà, bẹ́ ẹ ṣe ń fi àwọn ohun tí Jèhófà dá kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n, àwọn náà máa lè sọ bíi ti Ọba Dáfídì pé: “Jèhófà . . . kò sí iṣẹ́ kankan tó dà bíi tìrẹ.”—Sm. 86:8. w23.03 25 ¶16-17

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́