ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es25 ojú ìwé 67-77
  • July

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Tuesday, July 1
  • Wednesday, July 2
  • Thursday, July 3
  • Friday, July 4
  • Saturday, July 5
  • Sunday, July 6
  • Monday, July 7
  • Tuesday, July 8
  • Wednesday, July 9
  • Thursday, July 10
  • Friday, July 11
  • Saturday, July 12
  • Sunday, July 13
  • Monday, July 14
  • Tuesday, July 15
  • Wednesday, July 16
  • Thursday, July 17
  • Friday, July 18
  • Saturday, July 19
  • Sunday, July 20
  • Monday, July 21
  • Tuesday, July 22
  • Wednesday, July 23
  • Thursday, July 24
  • Friday, July 25
  • Saturday, July 26
  • Sunday, July 27
  • Monday, July 28
  • Tuesday, July 29
  • Wednesday, July 30
  • Thursday, July 31
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
es25 ojú ìwé 67-77

July

Tuesday, July 1

Ó lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ó ń ṣe rere, ó sì ń wo àwọn èèyàn sàn.—Ìṣe 10:38.

Gbogbo ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe fi hàn pé ó ń ronú bíi ti Bàbá ẹ̀, ó sì máa ń mọ nǹkan lára bíi ti Bàbá ẹ̀. (Jòh. 14:9) Kí la rí kọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe? Jésù àti Bàbá ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an torí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu kó lè fòpin sí ìyà tó ń jẹ wọ́n. Nígbà kan, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì kan kígbe pé kó ran àwọn lọ́wọ́. (Mát. 20:​30-34) Kíyè sí pé ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé “àánú wọn ṣe Jésù,” ó sì mú wọn lára dá. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “àánú wọn ṣe Jésù” jẹ́ ká rí i pé àánú wọn ṣe é gan-an débi pé ó mọ̀ ọ́n lára. Bí àánú àwọn èèyàn yẹn ṣe ṣe Jésù gan-an fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, ìyẹn ló jẹ́ kó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, kó sì tún wo alárùn ẹ̀tẹ̀ kan sàn. (Mát. 15:32; Máàkù 1:41) Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run tó ní “ojú àánú” àti Jésù Ọmọ rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa ń dùn wọ́n gan-an tí ìyà bá ń jẹ wá. (Lúùkù 1:78; 1 Pét. 5:7) Ẹ ò rí i pé ó wu Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ láti mú gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé kúrò! w23.04 3 ¶4-5

Wednesday, July 2

Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun tó burú. Ó ń ṣọ́ ẹ̀mí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀; ó ń gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.—Sm. 97:10.

Kò yẹ ká máa ka àwọn ìwé tàbí tẹ́tí sí èrò burúkú táwọn èèyàn ń gbé lárugẹ nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí. Tá a bá ń ka Bíbélì tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ déédéé, ohun tó dáa làá máa rò. Bákan náà, tá a bá ń lọ sípàdé, tá a sì ń wàásù déédéé, a ò ní máa ro èròkerò. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, Jèhófà ṣèlérí fún wa pé òun ò ní jẹ́ ká dán wa wò kọjá ohun tí a lè mú mọ́ra. (1 Kọ́r. 10:​12, 13) Ó yẹ ká máa gbàdúrà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lákòókò òpin tí nǹkan nira yìí. Jèhófà fẹ́ ká ‘tú ọkàn wa jáde níwájú rẹ̀’ tá a bá ń gbàdúrà. (Sm. 62:8) Máa yin Jèhófà, kó o sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ torí gbogbo ohun tó ṣe fún ẹ. Bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kó o nígboyà tó o bá ń wàásù. Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da ìṣòro èyíkéyìí, kó o sì lè borí ìdẹwò tó dojú kọ ẹ́. Má jẹ́ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni mú kó o má gbàdúrà sí Jèhófà mọ́. w23.05 7 ¶17-18

Thursday, July 3

Ẹ sì jẹ́ ká gba ti ara wa rò . . . , ká máa gba ara wa níyànjú.—Héb. 10:​24, 25.

Kí nìdí tá a fi máa ń lọ sípàdé ìjọ? Ìdí pàtàkì náà ni pé ká lè máa yin Jèhófà. (Sm. 26:12; 111:1) Ìdí míì tá a fi ń lọ sípàdé ni pé ká lè máa gba ara wa níyànjú lákòókò tí nǹkan le gan-an yìí. (1 Tẹs. 5:11) Torí náà, tá a bá nawọ́ láti dáhùn nípàdé, à ń yin Jèhófà nìyẹn, a sì tún ń gba ara wa níyànjú. Ṣùgbọ́n, ohun tó lè mú kó nira láti dáhùn nípàdé ni pé ẹ̀rù lè máa bà wá tàbí kó wù wá gan-an láti dáhùn léraléra, àmọ́ kí wọ́n máa fi bẹ́ẹ̀ pè wá. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn ìṣòro yìí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ká “máa gba ara wa níyànjú.” Tá a bá mọ̀ pé bá a ṣe ń dáhùn nípàdé tá a sì ń sọ ohun tá a gbà gbọ́ máa ń gbé àwọn ará ró, a ò ní máa bẹ̀rù láti dáhùn nípàdé. Tí wọn ò bá sì pè wá léraléra, ó yẹ kínú wa máa dùn pé àwọn míì náà láǹfààní láti dáhùn.—1 Pét. 3:8. w23.04 20 ¶1-3

Friday, July 4

Kí ó lọ sí Jerúsálẹ́mù, . . . kí ó sì tún ilé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kọ́.—Ẹ́sírà 1:3.

Àwọn Júù ti lo nǹkan bí àádọ́rin ọdún (70) nígbèkùn Bábílónì. Ọba wá pa àṣẹ kan pé kí gbogbo wọn pa dà sí Ísírẹ́lì ìlú ìbílẹ̀ wọn. (Ẹ́sírà 1:​2-4) Jèhófà nìkan ló lè mú kíyẹn ṣeé ṣe. Torí pé àwọn ará Bábílónì kì í fi àwọn tí wọ́n bá mú lẹ́rú sílẹ̀. (Àìsá. 14:​4, 17) Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti ṣẹ́gun Bábílónì, alákòóso tuntun sì sọ fáwọn Júù pé wọ́n lè pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Gbogbo àwọn Júù, pàápàá àwọn olórí ìdílé máa ní láti ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Ìpinnu náà ni bóyá wọ́n á kúrò ní Bábílónì tàbí wọ́n á dúró síbẹ̀. Àmọ́ kò rọrùn fún wọn láti ṣe ìpinnu yẹn. Torí pé ibi tí wọ́n ń lọ jìnnà, kò ní rọrùn fún ọ̀pọ̀ àwọn arúgbó láti rìnrìn àjò náà. Yàtọ̀ síyẹn, Bábílónì ni wọ́n bí ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù yẹn sí, wọn ò sì tíì gbé ibòmíì rí. Lójú wọn, ìlú àwọn baba ńlá wọn ni Ísírẹ́lì jẹ́. Àwọn Júù kan ti dolówó ní Bábílónì, torí náà ó lè ṣòro fún wọn láti fi ilé àti òwò wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì lọ máa gbé nílùú tí wọn ò mọ̀. w23.05 14 ¶1-2

Saturday, July 5

Kí ẹ̀yin náà múra sílẹ̀.—Mát. 24:44.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká ní ìfaradà, ká máa ṣàánú, ká sì ní ìfẹ́. Lúùkù 21:19 sọ pé: “Tí ẹ bá ní ìfaradà, ẹ máa lè pa ẹ̀mí yín mọ́.” Kólósè 3:12 náà sọ pé: ‘Ẹ fi àánú wọ ara yín láṣọ.’ 1 Tẹsalóníkà 4:​9, 10 náà tún sọ pé: “Ọlọ́run ti kọ́ yín láti máa nífẹ̀ẹ́ ara yín. . . . Àmọ́, ẹ̀yin ará, a rọ̀ yín pé kí ẹ máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n ti fi hàn pé àwọn nífaradà, pé àwọn ń ṣàánú, àwọn sì nífẹ̀ẹ́ la kọ gbogbo ẹsẹ Bíbélì yìí sí. Síbẹ̀, ó pọn dandan pé kí wọ́n túbọ̀ máa fi àwọn ànímọ́ yìí hàn. Ohun tó sì yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn. Kó o lè mọ bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, ronú nípa bí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe fi àwọn ànímọ́ yìí hàn. Lẹ́yìn náà, wàá rí bó o ṣe lè fara wé wọn, ìyẹn á sì jẹ́ kó o lè múra sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá. Tí ìpọ́njú ńlá bá fi máa bẹ̀rẹ̀, wàá ti kọ́ bó o ṣe lè fara da ọ̀pọ̀ nǹkan, o ò sì ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa jẹ́ kó o fi Jèhófà sílẹ̀. w23.07 2-3 ¶4, 8

Sunday, July 6

Ọ̀nà kan sì máa wà níbẹ̀, . . . Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.—Àìsá. 35:8.

Bóyá ẹni àmì òróró ni wá tàbí “àgùntàn mìíràn,” kò yẹ ká kúrò lójú “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” yẹn torí ó ń jẹ́ ká lè máa sin Jèhófà nìṣó báyìí, ó sì máa jẹ́ ká gbádùn àwọn ohun rere tí Ọlọ́run máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú nínú Ìjọba ẹ̀. (Jòh. 10:16) Láti ọdún 1919 S.K., àìmọye àwọn ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé ló ti kúrò nínú Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké ayé, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn lójú ọ̀nà ìjẹ́mímọ́ yẹn. Nígbà táwọn Júù ń kúrò ní Bábílónì, Jèhófà mú gbogbo ohun tó lè dí wọn lọ́wọ́ kúrò lójú ọ̀nà. (Àìsá. 57:14) Ṣé ohun kan náà ni Jèhófà ṣe lójú “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” lákòókò wa yìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú 1919, Jèhófà lo àwọn ọkùnrin tó bẹ̀rù rẹ̀ láti tún ọ̀nà náà ṣe, kí àwọn èèyàn lè kúrò nínú Bábílónì Ńlá. (Fi wé Àìsáyà 40:3.) Wọ́n ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láti tún ọ̀nà náà ṣe, kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lè kúrò nínú ẹ̀sìn èké, kí wọ́n lè wá dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà láti máa sìn ín níbi tí ìjọsìn mímọ́ ti pa dà bọ̀ sípò. w23.05 15-16 ¶8-9

Monday, July 7

Ẹ fi ayọ̀ sin Jèhófà. Ẹ fi igbe ayọ̀ wá síwájú rẹ̀.—Sm. 100:2.

Jèhófà fẹ́ ká máa fayọ̀ sin òun tọkàntọkàn. (2 Kọ́r. 9:7) Torí náà, ṣé ó wá yẹ ká máa ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ wa lè tẹ àfojúsùn kan tí ò bá tiẹ̀ wù wá? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó sọ pé: “Mò ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú.” (1 Kọ́r. 9:​25-27) Kódà láwọn ìgbà tí kò wu Pọ́ọ̀lù láti ṣe ohun tó tọ́, ó ṣohun tó tọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún un. Ṣé inú Jèhófà dùn sí ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni! Jèhófà sì bù kún un torí gbogbo ohun tó ṣe. (2 Tím. 4:​7, 8) Lọ́nà kan náà, inú Jèhófà máa dùn tó bá rí i pé à ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ wa lè tẹ àfojúsùn kan tí ò bá tiẹ̀ wù wá. Ó mọ̀ pé nígbà míì kì í ṣe torí àfojúsùn wa la ṣe ń ṣiṣẹ́ kára, àmọ́ ìfẹ́ tá a ní sóun la ṣe ń ṣe é. Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wa bó ṣe bù kún Pọ́ọ̀lù. (Sm. 126:5) Bá a sì ṣe ń rí i tí Jèhófà ń bù kún wa, ohun tá à ń ṣe yẹn lè bẹ̀rẹ̀ sí í wù wá. w23.05 29 ¶9-10

Tuesday, July 8

Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀.—1 Tẹs. 5:2.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àwọn tó máa pa run ní ọjọ́ Jèhófà wé àwọn tó ń sùn. Tẹ́nì kan bá ń sùn, kì í mọ ohun tó ń lọ láyìíká ẹ̀, kì í sì í mọ̀ pé àkókò ti ń lọ. Torí náà, wọn kì í mọ̀ tóhun pàtàkì kan tó yẹ kí wọ́n fiyè sí bá fẹ́ ṣẹlẹ̀. Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sùn lónìí torí pé wọn ò fiyè sí ọjọ́ Jèhófà tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé. (Róòmù 11:8) Wọn ò gbà pé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí fi hàn pé a ti ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” àti pé ìpọ́njú ńlá ò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀. (2 Pét. 3:​3, 4) Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká máa rántí ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún wa pé ká túbọ̀ máa wà lójúfò lójoojúmọ́ lásìkò wa yìí. (1 Tẹs. 5:6) Ó yẹ ká fara balẹ̀, ká sì máa gbé ọ̀rọ̀ yẹ̀ wò dáadáa. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò ní jẹ́ ká dá sọ́rọ̀ òṣèlú àti rògbòdìyàn tó ń lọ lágbègbè wa. Bí ọjọ́ Jèhófà ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn á túbọ̀ máa fúngun mọ́ wa pé ká dá sáwọn nǹkan yìí. Síbẹ̀, kò yẹ ká máa ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa dá wọn lóhùn. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa jẹ́ ká fara balẹ̀ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́.—Lúùkù 12:​11, 12. w23.06 10 ¶6-7

Wednesday, July 9

Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, jọ̀ọ́ rántí mi, jọ̀ọ́ fún mi lókun.—Oníd. 16:28.

Kí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ orúkọ náà Sámúsìn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun tó máa ń wá sí ẹ lọ́kàn ni ọkùnrin kan tó lágbára gan-an. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Àmọ́ Sámúsìn ṣe ìpinnu tí kò tọ́, àbájáde ẹ̀ ò sì dáa. Síbẹ̀, Jèhófà kíyè sí bí Sámúsìn ṣe sin òun tọkàntọkàn, ó sì jẹ́ kí wọ́n kọ ìtàn ẹ̀ sínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹ̀. Jèhófà lo Sámúsìn láti ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ribiribi ló sì gbé ṣe. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Sámúsìn kú, ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dárúkọ ẹ̀ mọ́ àwọn ọkùnrin tó nígbàgbọ́ àrà ọ̀tọ̀ nígbà tó ń kọ ìwé Hébérù. (Héb. 11:​32-34) Kò sí àní-àní pé ìtàn Sámúsìn máa fún wa níṣìírí. Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kódà láwọn ìgbà tó níṣòro. Àwọn nǹkan rere tá a rí kọ́ lára Sámúsìn máa fún wa níṣìírí gan-an, ó sì máa jẹ́ ká yẹra fáwọn àṣìṣe tó ṣe. w23.09 2 ¶1-2

Thursday, July 10

Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run.—Fílí. 4:6.

Ohun tó máa jẹ́ ká túbọ̀ nífaradà ni pé ká máa gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn nígbà gbogbo, ká sì máa sọ bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn wa fún un. (1 Tẹs. 5:17) O lè má ní àwọn ìṣòro tó ń bá ẹ fínra báyìí, àmọ́ ṣé o máa ń sọ pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí inú bá ń bí ẹ, tó ò bá mọ nǹkan tó yẹ kó o ṣe tàbí tí nǹkan bá tojú sú ẹ? Tó bá ti mọ́ ẹ lára báyìí láti máa bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá láwọn ìṣòro kéékèèké, á rọrùn fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá láwọn ìṣòro ńlá lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ bó ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, ó sì mọ ìgbà tó yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 27:​1, 3) Tá a bá ń fara da àwọn ìṣòro wa báyìí, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti fara da àwọn ìṣòro tá a máa ní nígbà ìpọ́njú ńlá. (Róòmù 5:3) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló sọ pé táwọn bá fara da ìṣòro kan, ó máa ń jẹ́ káwọn fara da àwọn ìṣòro míì tó bá yọjú. Gbogbo ìgbà tí Jèhófà bá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro ni ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ ń lágbára, ó sì dá wọn lójú pé Jèhófà máa ran àwọn lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú. Ìgbàgbọ́ yìí ló ń jẹ́ kí wọ́n fara da ìṣòro míì tó bá yọjú.—Jém. 1:​2-4. w23.07 3 ¶7-8

Friday, July 11

Màá ro tìẹ.—Jẹ́n. 19:21.

Torí pé Jèhófà nírẹ̀lẹ̀, tó sì láàánú, ó máa ń fòye báni lò. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ nígbà tó fẹ́ pa àwọn èèyàn búburú tó wà nílùú Sódómù run. Jèhófà rán àwọn áńgẹ́lì ẹ̀ pé kí wọ́n sọ fún Lọ́ọ̀tì ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́ pé kó sá kúrò nílùú yẹn lọ sórí òkè ńlá kan. Àmọ́, ẹ̀rù ń ba Lọ́ọ̀tì láti sá lọ síbẹ̀. Torí náà, ó bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun àti ìdílé òun sá lọ sí Sóárì, ìyẹn ìlú kékeré kan tí Jèhófà ti sọ pé òun máa pa run. Jèhófà lè sọ pé dandan ni kí Lọ́ọ̀tì ṣe ohun tóun sọ fún un. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gba tiẹ̀ rò, ó sì dá ìlú Sóárì sí torí tiẹ̀. (Jẹ́n. 19:​18-22) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà tún fàánú hàn sáwọn ará ìlú Nínéfè. Ó ní kí wòlíì Jónà lọ sọ fáwọn ará ìlú náà pé òun máa pa àwọn àti ìlú náà run nítorí ìwà burúkú wọn. Àmọ́ nígbà táwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà, Jèhófà ṣàánú wọn, kò sì pa ìlú náà run.—Jónà 3:​1, 10; 4:​10, 11. w23.07 21 ¶5

Saturday, July 12

Wọ́n pa [Jèhóáṣì] . . . , àmọ́ wọn ò sin ín sí ibi tí wọ́n ń sin àwọn ọba sí.—2 Kíró. 24:25.

Kí la kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jèhóáṣì? Ṣe ni Jèhóáṣì dà bí igi ńlá kan tí gbòǹgbò ẹ̀ ò lágbára, tí wọ́n wá fi igi kan tì í kó má bàa ṣubú. Tí atẹ́gùn bá fẹ́, ṣe ni igi náà máa wó lulẹ̀. Nígbà tí Jèhóádà tó ń ran Jèhóáṣì lọ́wọ́ kú, Jèhóáṣì bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sáwọn tí ò sin Jèhófà mọ́, bí òun náà ò ṣe sin Jèhófà mọ́ nìyẹn. Àfiwé yìí jẹ́ ká rí i pé tá a bá fẹ́ bẹ̀rù Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́, ìrànlọ́wọ́ táwọn tá a jọ ń sin Jèhófà àtàwọn ará ilé wa ń ṣe fún wa nìkan kọ́ ló yẹ ká gbára lé. Kí àjọṣe wa àti Jèhófà lè máa lágbára sí i, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, ká máa ṣàṣàrò, ká sì máa gbàdúrà. Ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún un. (Jer. 17:​7, 8; Kól. 2:​6, 7) Jèhófà ò retí pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe wà nínú Oníwàásù 12:​13, ó sọ pé: “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, nítorí èyí ni gbogbo ojúṣe èèyàn.” Tá a bá ń bẹ̀rù Ọlọ́run, àá lè fara da àwọn àdánwò tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò sóhun tó máa ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́. w23.06 19 ¶17-19

Sunday, July 13

Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.—Ìfi. 21:5.

Ohun tó bẹ̀rẹ̀ ẹsẹ karùn-ún ni pé: “Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ sọ pé.” (Ìfi. 21:5a) Ọ̀rọ̀ yìí ló ṣáájú ọ̀kan lára ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú ìwé Ìfihàn. Kì í ṣe áńgẹ́lì alágbára kan, kódà kì í ṣe Jésù tó ti jíǹde ló ṣe ìlérí yìí, Jèhófà fúnra ẹ̀ ló ṣe ìlérí náà! Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló sọ ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé a lè gba àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé e nínú ẹsẹ yẹn gbọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Torí pé Jèhófà “kò lè parọ́.” (Títù 1:2) Torí náà, ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìfihàn 21:​5, 6 máa ṣẹ. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà “Wò ó!” Léraléra ni wọ́n lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “wò ó!” nínú ìwé Ìfihàn. Gbólóhùn wo ni Jèhófà sọ tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ náà “Wò ó!”? Ó sọ pé: “Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” Òótọ́ ni pé ọjọ́ iwájú ni Jèhófà máa ṣe àwọn nǹkan tó sọ yìí, àmọ́ torí pé ó dá a lójú pé òun máa ṣe é, ìdí nìyẹn tó fi sọ ọ́ bíi pé àwọn nǹkan náà ti ń ṣẹ.—Àìsá. 46:10. w23.11 3-4 ¶7-8

Monday, July 14

Ó bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.— Mát. 26:75.

Àpọ́sítélì Pétérù láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ń bá yí. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan. Nígbà tí Jésù sọ pé òun máa jìyà òun sì máa kú bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́ lẹ̀, ńṣe ni Pétérù sọ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ní ṣẹlẹ̀ sí Jésù. (Máàkù 8:​31-33) Yàtọ̀ síyẹn, léraléra ni Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù jiyàn nípa ẹni tó máa jẹ́ olórí láàárín wọn. (Máàkù 9:​33, 34) Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, Pétérù gé etí ọkùnrin kan dà nù láìjáfara. (Jòh. 18:10) Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, ẹ̀rù ba Pétérù, ó sì sẹ́ Jésù ọ̀rẹ́ ẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta. (Máàkù 14:​66-72) Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí Pétérù sunkún gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ti rẹ̀wẹ̀sì, Jésù ò jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ sú òun. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fún Pétérù láǹfààní láti fi hàn pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ òun. Torí náà, Jésù ní kí Pétérù máa fìrẹ̀lẹ̀ bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. (Jòh. 21:​15-17) Pétérù sì múra tán láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún un. Torí náà, ó wà lára àwọn tí Jèhófà kọ́kọ́ fi ẹ̀mí mímọ́ yàn ní Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì. w23.09 22 ¶6-7

Tuesday, July 15

Máa bójú tó àwọn àgùntàn mi kéékèèké.—Jòh. 21:16.

Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn alàgbà nímọ̀ràn pé kí wọ́n “máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run.” (1 Pét. 5:​1-4) Tó bá jẹ́ pé alàgbà ni ẹ́, ó dájú pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ, ó sì wù ẹ́ kó o máa bójú tó wọn. Àmọ́ nígbà míì, ọwọ́ ẹ lè dí tàbí kó rẹ̀ ẹ́ débi pé o ò lè bójú tó àwọn ará. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe? Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà. Pétérù sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe ìránṣẹ́, kó ṣe é bí ẹni tó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń fúnni.” (1 Pét. 4:11) Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan níṣòro tó jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ẹ̀. Àmọ́, máa rántí pé Jésù Kristi tó jẹ́ “olórí olùṣọ́ àgùntàn” máa ṣe ju ohun tó o lè ṣe fún wọn. Ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí, á sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ayé tuntun. Ohun tí Jèhófà fẹ́ kẹ́yin alàgbà máa ṣe ni pé kẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, kẹ́ ẹ máa bójú tó wọn, kẹ́ ẹ sì “jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo.” w23.09 29-30 ¶13-14

Wednesday, July 16

Jèhófà mọ̀ pé èrò àwọn ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.—1 Kọ́r. 3:20.

Ó yẹ ká yẹra fún ọgbọ́n èèyàn tá a bá fẹ́ ṣe ohunkóhun. Tá a bá ń ronú bí àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà ṣe ń ronú, ó lè jẹ́ ká pa Jèhófà àtàwọn ìlànà ẹ̀ tì. (1 Kọ́r. 3:19) “Ọgbọ́n ayé yìí” máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Àwọn Kristẹni kan tó wà nílùú Págámù àti Tíátírà ń bọ̀rìṣà, wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe bíi tàwọn ará ìlú náà. Jésù bá ìjọ méjèèjì yìí wí lọ́nà tó le torí pé wọ́n gba ìṣekúṣe láyè. (Ìfi. 2:​14, 20) Bákan náà lónìí, àwọn èèyàn ń fúngun mọ́ wa pé ká ṣàìgbọràn sí Jèhófà, àwọn ará ilé wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa sì lè fẹ́ ká ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ pé kò sóhun tó burú tá a bá ṣèṣekúṣe àti pé àwọn ìlànà Bíbélì ò bóde mu mọ́. Nígbà míì, a lè máa rò pé Jèhófà ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ohun tó fẹ́ ká ṣe. Kódà, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀.—1 Kọ́r. 4:6. w23.07 16 ¶10-11

Thursday, July 17

Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.—Òwe 17:17.

Màríà ìyá Jésù nílò okun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ṣègbéyàwó, ó máa lóyún. Kò tíì tọ́mọ rí, àmọ́ òun ló máa tọ́ ọmọ tó máa di Mèsáyà. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé Màríà kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí, báwo ló ṣe máa ṣàlàyé fún Jósẹ́fù àfẹ́sọ́nà ẹ̀ pé òun ti lóyún? (Lúùkù 1:​26-33) Báwo ni Màríà ṣe rí okun tó nílò gbà? Ó jẹ́ káwọn ẹlòmíì ran òun lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ní kí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì túbọ̀ ṣàlàyé iṣẹ́ náà fún òun. (Lúùkù 1:34) Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó rìnrìn àjò lọ sí “ilẹ̀ olókè” ní Júdà láti lọ wo mọ̀lẹ́bí ẹ̀ Èlísábẹ́tì. Èlísábẹ́tì gbóríyìn fún Màríà, Jèhófà sì fẹ̀mí ẹ̀ darí Èlísábẹ́tì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá nípa ọmọ tí Màríà máa bí. (Lúùkù 1:​39-45) Màríà sọ pé Jèhófà “ti fi apá rẹ̀ ṣe ohun tó lágbára.” (Lúùkù 1:​46-51) Torí náà, Jèhófà lo Gébúrẹ́lì àti Èlísábẹ́tì láti fún Màríà lókun. w23.10 14-15 ¶10-12

Friday, July 18

Ó mú ká di ìjọba kan, àlùfáà fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀.—Ìfi. 1:6.

Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ yan díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi, wọ́n sì ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) yìí máa jẹ́ àlùfáà pẹ̀lú Jésù. (Ìfi. 14:1) Ibi Mímọ́ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn náà ṣàpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe fẹ̀mí yàn wọ́n láti jẹ́ ọmọ ẹ̀ nígbà tí wọ́n wà láyé. (Róòmù 8:​15-17) Ibi Mímọ́ Jù Lọ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn náà ṣàpẹẹrẹ ọ̀run, ibi tí Jèhófà ń gbé. “Aṣọ ìdábùú” tó pín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ṣàpẹẹrẹ ara Jésù tí ò jẹ́ kó lè wọlé sọ́run láti ṣiṣẹ́ Àlùfáà Àgbà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí. Jésù fi ara ẹ̀ rúbọ nítorí aráyé, ohun tó ṣe yìí mú kó ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn láti gba ìyè lọ́run. Kí wọ́n lè gba èrè wọn lọ́run, àwọn náà ò ní gbé ẹran ara wọn lọ sọ́run.—Héb. 10:​19, 20; 1 Kọ́r. 15:50. w23.10 28 ¶13

Saturday, July 19

Àkókò ò ní tó tí n bá ní kí n máa sọ̀rọ̀ nípa Gídíónì.—Héb. 11:32.

Nígbà táwọn ọmọ Éfúráímù bínú sí Gídíónì gidigidi, kò gbaná jẹ, kò sì fìbínú sọ̀rọ̀ sí wọn. (Oníd. 8:​1-3) Ó fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ torí ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, ó sì fọgbọ́n yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àwọn alàgbà tó gbọ́n máa ń fara wé Gídíónì. Táwọn èèyàn bá ṣàríwísí wọn, wọ́n máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, wọn kì í sì í gbaná jẹ. (Jém. 3:13) Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ló ń mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ. Nígbà táwọn èèyàn ń yin Gídíónì torí pé ó ṣẹ́gun àwọn ará Mídíánì, Jèhófà ló fìyìn fún. (Oníd. 8:​22, 23) Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè fara wé Gídíónì? Ẹ lè ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́ ẹ bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ló ń ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tẹ́ ẹ̀ ń ṣe. (1 Kọ́r. 4:​6, 7) Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá gbóríyìn fún alàgbà kan torí àsọyé tó sọ, ó yẹ kó jẹ́ káwọn ará mọ̀ pé inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lòun ti mú ohun tóun sọ tàbí kó sọ pé àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ètò Ọlọ́run ń fún wa ló ran òun lọ́wọ́. Ó yẹ kẹ́yin alàgbà máa kíyè sára tẹ́ ẹ bá ń kọ́ni, kó má jẹ́ pé ẹ̀yin làwọn èèyàn á máa kan sárá sí, dípò kí wọ́n fògo fún Jèhófà. w23.06 4 ¶7-8

Sunday, July 20

Èrò mi yàtọ̀ sí èrò yín.—Àìsá. 55:8.

Tá ò bá rí àwọn nǹkan tá à ń béèrè nínú àdúrà wa gbà, ó yẹ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè kan. Àkọ́kọ́ ni pé ‘Ṣé ohun tó tọ́ ni mò ń béèrè?’ Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń ronú pé a mọ ohun tó dáa jù fún wa. Àmọ́ àwọn ohun tá à ń béèrè yẹn lè má ṣe wá láǹfààní. Tá a bá ń gbàdúrà nípa ìṣòro kan, ó ṣeé ṣe kí ọ̀nà míì wà láti gbà yanjú ìṣòro náà tó dáa ju ohun tá a rò lọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn nǹkan míì tá a béèrè lè má bá ìfẹ́ Jèhófà mu. (1 Jòh. 5:14) Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo àwọn òbí tí wọ́n ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ọmọ àwọn dúró sínú òtítọ́. Àdúrà tó dáa nìyẹn. Síbẹ̀, Jèhófà ò ní fipá mú ẹnikẹ́ni nínú wa láti jọ́sìn òun. Ó fẹ́ kí gbogbo wa títí kan àwọn ọmọ wa pinnu pé òun làá máa sìn. (Diu. 10:​12, 13; 30:​19, 20) Torí náà, ohun tó yẹ kí wọ́n bẹ Jèhófà ni pé kó jẹ́ káwọn kọ́ ọmọ àwọn lọ́nà tá á fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tá á sì jọ́sìn ẹ̀.—Òwe 22:6; Éfé. 6:4. w23.11 21 ¶5; 23 ¶12

Monday, July 21

Ẹ máa . . . tu ara yín nínú.—1 Tẹs. 4:18.

Tá a bá ń tu àwọn èèyàn nínú, báwo nìyẹn ṣe máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn? Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò tí wọ́n tú sí ‘tù nínú’ nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní túmọ̀ sí “kí ẹnì kan dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹni tó níṣòro tó le gan-an, kó sì fún un níṣìírí.” Tá a bá tu arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú, ńṣe là ń ràn án lọ́wọ́ kó lè máa rìn ní ọ̀nà ìyè nìṣó. Torí náà, gbogbo ìgbà tá a bá dúró ti àwọn ará là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. (2 Kọ́r. 7:​6, 7, 13) Ẹni tó lójú àánú àti ẹni tó máa ń tu àwọn èèyàn nínú ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ẹni tó lójú àánú máa ń tu àwọn èèyàn nínú, ó sì máa ń fẹ́ yanjú ìṣòro wọn. Torí náà, tá a bá lójú àánú, àá máa tu àwọn èèyàn nínú. Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé olójú àánú ni Jèhófà, ìdí nìyẹn tó fi máa ń tu àwọn èèyàn nínú. Ó pe Jèhófà ní “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 Kọ́r. 1:3. w23.11 9-10 ¶8-10

Tuesday, July 22

Ẹ jẹ́ ká máa yọ̀ nígbà tí a bá wà nínú ìpọ́njú.—Róòmù 5:3.

Gbogbo àwa ọmọlẹ́yìn Kristi la máa rí ìpọ́njú. Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó sọ fáwọn tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a máa ń sọ fún yín pé a máa ní ìpọ́njú, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn.” (1 Tẹs. 3:4) Ó sì sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì pé: “A fẹ́ kí ẹ mọ̀ nípa ìpọ́njú tó bá wa . . . a ò tiẹ̀ mọ̀ pé ẹ̀mí wa ò ní bọ́.” (2 Kọ́r. 1:8; 11:​23-27) Àwa Kristẹni lónìí náà mọ̀ pé ìgbàkigbà ni ìpọ́njú lè dé bá wa. (2 Tím. 3:12) Àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ lè máa gbógun tì ẹ́ torí pé o nígbàgbọ́ nínú Jésù, o sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. Ṣé àwọn ará ibi iṣẹ́ ẹ ti ń fúngun mọ́ ẹ torí pé o jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo? (Héb. 13:18) Àbí àwọn aláṣẹ ìjọba ń ta kò ẹ́ torí pé ò ń wàásù? Láìka ìpọ́njú yòówù kó dé bá wa sí, Pọ́ọ̀lù sọ pé ká máa yọ̀. w23.12 10-11 ¶9-10

Wednesday, July 23

Wàhálà ńlá lẹ kó mi sí yìí.—Jẹ́n. 34:30.

Ọ̀pọ̀ ìṣòro ni Jékọ́bù fara dà. Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù tó ń jẹ́ Síméónì àti Léfì dójú ti ilé bàbá wọn, wọ́n sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, Réṣẹ́lì tí Jékọ́bù fẹ́ràn gan-an kú nígbà tó fẹ́ bímọ kejì. Nítorí ìyàn tó mú ní ilẹ̀ náà, ó di dandan kí Jékọ́bù àti ìdílé ẹ̀ ṣí lọ sí Íjíbítì nígbà tó darúgbó. (Jẹ́n. 35:​16-19; 37:28; 45:​9-11, 28) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìṣòro dé bá Jékọ́bù, kò fi Jèhófà sílẹ̀, ó nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí tó ṣe, Jèhófà náà sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun wà pẹ̀lú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà bù kún Jékọ́bù, ó sì jẹ́ kó lóhun ìní tó pọ̀. Ó dájú pé inú Jékọ́bù máa dùn, ó sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà gan-an nígbà tó pa dà rí Jósẹ́fù tó rò pé ó ti kú! Torí pé àjọṣe tó dáa wà láàárín Jékọ́bù àti Jèhófà, ìyẹn jẹ́ kó lè borí àwọn ìṣòro tó ní. (Jẹ́n. 30:43; 32:​9, 10; 46:​28-30) Táwa náà bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, àá borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá wa. w23.04 15 ¶6-7

Thursday, July 24

Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní.—Sm. 23:1.

Sáàmù 23 jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń bójú tó wa. Dáfídì tó kọ Sáàmù yìí ṣàlàyé bí ìfẹ́ tó wà láàárín òun àti Jèhófà tó ń ṣọ́ ọ bí Olùṣọ́ àgùntàn ṣe lágbára tó. Ọkàn Dáfídì balẹ̀ bó ṣe jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ òun sọ́nà, ìyẹn sì jẹ́ kó gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. Torí náà, ó dá Dáfídì lójú pé ojoojúmọ́ ni Jèhófà á máa nífẹ̀ẹ́ òun. Kí ló mú kó dá a lójú? Dáfídì gbà pé Jèhófà bójú tó òun dáadáa torí gbogbo ìgbà ni Jèhófà pèsè ohun tó nílò. Yàtọ̀ síyẹn, Dáfídì gbádùn bóun àti Jèhófà ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́, ó sì tún rí ojúure ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi dá a lójú pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa bójú tó òun. Dáfídì gbà pé ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà ní sóun máa jẹ́ kóun borí ìṣòro yòówù kóun ní, ó sì máa jẹ́ kóun láyọ̀, kóun sì ní ìtẹ́lọ́rùn.—Sm. 16:11. w24.01 28-29 ¶12-13

Friday, July 25

Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.—Mát. 28:20.

Àtìgbà Ogun Àgbáyé Kejì làwa èèyàn Jèhófà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti ń gbádùn àlàáfíà déwọ̀n àyè kan, a sì lómìnira láti wàásù. Kódà, kárí ayé làwa èèyàn Jèhófà ti ń wàásù, ọ̀pọ̀ èèyàn sì ti wá mọ Jèhófà. Lónìí, àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí náà ń jẹ́ kí Kristi tọ́ àwọn sọ́nà. Tí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu nípa ohun táwọn ará máa ṣe, wọ́n máa ń fẹ́ kó jẹ́ pé ohun tí Jèhófà àti Kristi fẹ́ làwọn máa sọ fáwọn ará. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣèpinnu náà tán, wọ́n máa ń ní káwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà fi jíṣẹ́ fáwọn ará nínú ìjọ. Ó ṣe tán, àwọn alàgbà tó jẹ́ ẹni àmì òróró títí kan gbogbo àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ ló wà ní “ọwọ́ ọ̀tún” Kristi. (Ìfi. 2:1) Ká sòótọ́, aláìpé làwọn alàgbà yìí, wọ́n sì máa ń ṣàṣìṣe. Àwọn ìgbà kan wà tí Mósè àti Jóṣúà ṣàṣìṣe, àwọn àpọ́sítélì náà sì ṣàṣìṣe. (Nọ́ń. 20:12; Jóṣ. 9:​14, 15; Róòmù 3:23) Síbẹ̀, Kristi ṣì ń fìfẹ́ bójú tó ẹrú olóòótọ́ àtàwọn alàgbà, á sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó. Torí náà, kò sídìí tí ò fi yẹ ká ṣe ohun tí wọ́n bá sọ fún wa torí Kristi ló ń darí wọn. w24.02 23-24 ¶13-14

Saturday, July 26

Ẹ máa fara wé Ọlọ́run, bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ.—Éfé. 5:1.

Lónìí, a lè múnú Jèhófà dùn tá a bá ń dúpẹ́ oore tó ṣe wá, tá a sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Ohun tó ṣe pàtàkì jù tá a bá ń wàásù ni pé ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti wá sin Jèhófà, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Jém. 4:8) Inú wa máa ń dùn láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, onídàájọ́ òdodo ni, ó gbọ́n, ó lágbára, ó sì tún láwọn ànímọ́ míì tó jẹ́ ká lè sún mọ́ ọn. A tún máa ń yin Jèhófà, a sì máa ń múnú ẹ̀ dùn bá a ṣe ń sapá láti fara wé e. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn máa kíyè sí pé ìwà wa yàtọ̀ sí tàwọn tí ò mọ Jèhófà nínú ayé burúkú yìí. (Mát. 5:​14-16) Bá a ṣe ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́, á ṣeé ṣe fún wa láti ṣàlàyé ìdí tí ìwà wa fi yàtọ̀, ìyẹn á sì mú káwọn olóòótọ́ ọkàn wá sin Jèhófà. Tá a bá ń yin Jèhófà lọ́nà yìí, inú ẹ̀ á máa dùn sí wa.—1 Tím. 2:​3, 4. w24.02 10 ¶7

Sunday, July 27

Kó lè gbani níyànjú, kó sì báni wí.—Títù 1:9.

Kó o tó lè di ọkùnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, o gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Ìyẹn máa jẹ́ kó o lè bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún ẹ dáadáa nínú ìjọ, á jẹ́ kó o ríṣẹ́ tí wàá fi máa bójú tó ara ẹ tàbí ìdílé ẹ, á sì jẹ́ kí àjọṣe àárín ìwọ àtàwọn ẹlòmíì gún. Bí àpẹẹrẹ, kọ́ bó o ṣe lè mọ̀wé kọ, kó o sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa. Bíbélì sọ pé tí ẹnì kan bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ tó sì ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀, ó máa láyọ̀, gbogbo ohun tó bá ń ṣe á sì máa yọrí sí rere. (Sm. 1:​1-3) Torí náà, tó bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, á máa ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́, á sì jẹ́ kó mọ bó ṣe máa fi àwọn nǹkan tó ń kọ́ sílò. (Òwe 1:​3, 4) Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nílò àwọn ọkùnrin tó lè fi Bíbélì kọ́ni dáadáa, kí wọ́n sì fi gbà wọ́n níyànjú. Tó o bá mọ̀wé kọ tó o sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa, wàá lè múra àsọyé àti ìdáhùn tó máa gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará ró, tí wọ́n á sì rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, wàá lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó máa mú kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára, wàá sì lè fún àwọn ẹlòmíì níṣìírí. w23.12 26-27 ¶9-11

Monday, July 28

Ẹni tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín tóbi ju ẹni tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ayé.—1 Jòh. 4:4.

Tẹ́rù bá ń bà ẹ́, máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe lọ́jọ́ iwájú nígbà tí Sátánì ò ní sí mọ́. Àwòrán tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ agbègbè ọdún 2014 jẹ́ ká rí bí bàbá kan ṣe ń jíròrò ohun tó wà nínú 2 Tímótì 3:​1-5 pẹ̀lú ìdílé ẹ̀, ó sì sọ ọ́ bíi pé àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nínú Párádísè ló ń sọ. Ó sọ pé: “Inú ayé tuntun ni inú wa ti máa dùn jù. Àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, wọ́n máa mọ̀wọ̀n ara wọn, wọ́n máa nírẹ̀lẹ̀, wọ́n á máa yin Ọlọ́run, àwọn ọmọ á máa gbọ́ràn sí òbí wọn lẹ́nu, wọ́n á máa moore, wọ́n á jẹ́ olóòótọ́, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ìdílé wọn gan-an, àwọn èèyàn á máa gbọ́ ara wọn yé, wọ́n á máa sọ̀rọ̀ tó dáa nípa àwọn ẹlòmíì, wọ́n á ní ìkóra-ẹni-níjàánu, wọ́n máa níwà tútù, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ohun rere, wọ́n á ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, wọ́n á máa fòye báni lò, wọn ò ní máa gbéra ga, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run dípò ìgbádùn, wọ́n á máa fọkàn sin Ọlọ́run, irú àwọn èèyàn yìí ni kó o máa bá ṣọ̀rẹ́.” Ṣé ìwọ àti ìdílé ẹ tàbí àwọn ará míì jọ máa ń sọ bí nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun? w24.01 6 ¶13-14

Tuesday, July 29

Mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.—Lúùkù 3:22.

Ó dájú pé ọkàn wa balẹ̀ gan-an bá a ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí gbogbo àwa èèyàn ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Inú Jèhófà ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀.” (Sm. 149:4) Àmọ́ nígbà míì, àwọn kan máa ń rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n sì máa ń bi ara wọn pé, ‘Ṣé inú Jèhófà ń dùn sí mi ṣá?’ Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn náà rẹ̀wẹ̀sì láwọn ìgbà kan, ó sì ṣòro fún wọn láti gbà pé inú Jèhófà ń dùn sí wọn. (1 Sám. 1:​6-10; Jóòbù 29:​2, 4; Sm. 51:11) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé inú Jèhófà máa ń dùn sí àwa èèyàn aláìpé. Àmọ́ kí la gbọ́dọ̀ ṣe kínú ẹ̀ tó lè dùn sí wa? A gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, ká sì ṣèrìbọmi. (Jòh. 3:16) Ìyẹn lá fi hàn pé a ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, a sì ti ṣèlérí fún Ọlọ́run pé ìfẹ́ rẹ̀ la máa ṣe. (Ìṣe 2:38; 3:19) Inú Jèhófà máa ń dùn gan-an tá a bá ṣe àwọn nǹkan yìí ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ, inú Jèhófà máa dùn sí wa, á sì kà wá sí ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́.—Sm. 25:14. w24.03 26 ¶1-2

Wednesday, July 30

A ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.—Ìṣe 4:20.

Ó yẹ káwa náà máa wàásù bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí ìjọba bá tiẹ̀ sọ pé ká má wàásù mọ́. Ó yẹ kó dá àwa náà lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Torí náà, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ nígboyà àti ọgbọ́n. Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro ẹ. Ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń fara da àìsàn, ìdààmú ọkàn, ikú èèyàn wa kan, ìṣòro ìdílé tó le gan-an, inúnibíni àtàwọn ìṣòro míì. Àwọn nǹkan bí àjàkálẹ̀ àrùn àti ogun sì ti mú káwọn nǹkan yìí túbọ̀ nira fáwọn ará wa. Torí náà, sọ gbogbo bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà. Sọ ìṣòro tó o ní fún Jèhófà bó o ṣe máa sọ fún ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé Jèhófà máa “gbé ìgbésẹ̀ nítorí rẹ.” (Sm. 37:​3, 5) Tá a bá tẹra mọ́ àdúrà, ó máa jẹ́ ká “fara da ìpọ́njú.” (Róòmù 12:12) Jèhófà mọ ohun táwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ń bá yí, ‘ó sì máa ń gbọ́ igbe wa tá a bá ní kó ràn wá lọ́wọ́.’—Sm. 145:​18, 19. w23.05 5-6 ¶12-15

Thursday, July 31

Ẹ máa wádìí dájú ohun tí Olúwa tẹ́wọ́ gbà.—Éfé. 5:10.

Tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, ó yẹ ká máa fi òye mọ “ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́,” ká sì ṣe é. (Éfé. 5:17) Tá a bá ń wá àwọn ìlànà Bíbélì tó bá ipò wa mu, ńṣe là ń fi hàn pé a fẹ́ kí Ọlọ́run tọ́ wa sọ́nà lórí ọ̀rọ̀ náà. Tá a bá sì fi àwọn ìlànà náà sílò, àá ṣe ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn. Sátánì “ẹni burúkú náà” máa fẹ́ ká máa fi àkókò wa ṣòfò lórí àwọn nǹkan táyé ń gbé lárugẹ débi tá ò fi ní ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run mọ́. (1 Jòh. 5:19) Tí Kristẹni kan ò bá ṣọ́ra, ó máa fi àwọn nǹkan tara, ilé ìwé àti iṣẹ́ ṣáájú àwọn nǹkan tó yẹ kó máa ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe nìyẹn á fi hàn pé òun náà ti ń ronú bíi tàwọn èèyàn ayé. Lóòótọ́, kò sóhun tó burú nínú àwọn nǹkan yìí, àmọ́ kò yẹ ká jẹ́ kí wọ́n gba ipò àkọ́kọ́ láyé wa. w24.03 24 ¶16-17

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́