ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Kọ́ríńtì 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Kọ́ríńtì

      • Ó yẹ kí ìríjú jẹ́ olóòótọ́ (1-5)

      • Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ tó jẹ́ Kristẹni (6-13)

        • ‘Má ṣe kọjá ohun tó wà lákọsílẹ̀’ (6)

        • Àwọn Kristẹni jẹ́ ìran àpéwò (9)

      • Pọ́ọ̀lù ń bójú tó àwọn tó jẹ́ ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí (14-21)

1 Kọ́ríńtì 4:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọmọ abẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 13:11; Ro 16:25, 26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2012, ojú ìwé 11-12

    8/1/2000, ojú ìwé 14-16

1 Kọ́ríńtì 4:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2012, ojú ìwé 12-13

1 Kọ́ríńtì 4:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kóòtù.”

1 Kọ́ríńtì 4:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún A5.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 21:2; Ro 14:10; Heb 4:13

1 Kọ́ríńtì 4:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 7:1
  • +Owe 10:9; 2Kọ 10:18; 1Ti 5:24, 25

1 Kọ́ríńtì 4:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣàpèjúwe.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 1:12
  • +Ro 12:3; 2Kọ 12:20; 3Jo 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2008, ojú ìwé 7

1 Kọ́ríńtì 4:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 3:27

1 Kọ́ríńtì 4:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 20:4, 6
  • +2Ti 2:12; Ifi 3:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2008, ojú ìwé 22

    1/15/1994, ojú ìwé 17-18

1 Kọ́ríńtì 4:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 8:36; 1Kọ 15:32; 2Kọ 6:4, 9
  • +Heb 10:33

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2009, ojú ìwé 24

    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba,

    8/2001, ojú ìwé 1

    Jí!,

    8/8/1998, ojú ìwé 17

1 Kọ́ríńtì 4:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 3:18

1 Kọ́ríńtì 4:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk.,“a wà ní ìhòòhò.”

  • *

    Tàbí “gbá wa káàkiri.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Flp 4:12
  • +2Kọ 11:27
  • +Iṣe 14:19; 23:2; 2Kọ 11:24

1 Kọ́ríńtì 4:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 18:3; 20:34; 1Tẹ 2:9
  • +Ro 12:14; 1Pe 3:9
  • +Mt 5:44

1 Kọ́ríńtì 4:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “a wá ojú rere.”

  • *

    Tàbí “ìdọ̀tí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Pe 2:23

1 Kọ́ríńtì 4:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “olùkọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ga 4:19; 1Tẹ 2:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    8/1/1993, ojú ìwé 15

1 Kọ́ríńtì 4:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 11:1; Flp 3:17; 1Tẹ 1:6

1 Kọ́ríńtì 4:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “àwọn ọ̀nà mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ti 1:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2018, ojú ìwé 14

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2017, ojú ìwé 30-31

1 Kọ́ríńtì 4:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún A5.

1 Kọ́ríńtì 4:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 13:10

Àwọn míì

1 Kọ́r. 4:1Mt 13:11; Ro 16:25, 26
1 Kọ́r. 4:4Owe 21:2; Ro 14:10; Heb 4:13
1 Kọ́r. 4:5Mt 7:1
1 Kọ́r. 4:5Owe 10:9; 2Kọ 10:18; 1Ti 5:24, 25
1 Kọ́r. 4:61Kọ 1:12
1 Kọ́r. 4:6Ro 12:3; 2Kọ 12:20; 3Jo 9
1 Kọ́r. 4:7Jo 3:27
1 Kọ́r. 4:8Ifi 20:4, 6
1 Kọ́r. 4:82Ti 2:12; Ifi 3:21
1 Kọ́r. 4:9Ro 8:36; 1Kọ 15:32; 2Kọ 6:4, 9
1 Kọ́r. 4:9Heb 10:33
1 Kọ́r. 4:101Kọ 3:18
1 Kọ́r. 4:11Flp 4:12
1 Kọ́r. 4:112Kọ 11:27
1 Kọ́r. 4:11Iṣe 14:19; 23:2; 2Kọ 11:24
1 Kọ́r. 4:12Iṣe 18:3; 20:34; 1Tẹ 2:9
1 Kọ́r. 4:12Ro 12:14; 1Pe 3:9
1 Kọ́r. 4:12Mt 5:44
1 Kọ́r. 4:131Pe 2:23
1 Kọ́r. 4:15Ga 4:19; 1Tẹ 2:11
1 Kọ́r. 4:161Kọ 11:1; Flp 3:17; 1Tẹ 1:6
1 Kọ́r. 4:172Ti 1:13
1 Kọ́r. 4:212Kọ 13:10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Kọ́ríńtì 4:1-21

Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì

4 Ó yẹ kí àwọn èèyàn kà wá sí ìránṣẹ́* Kristi àti ìríjú àwọn àṣírí mímọ́ Ọlọ́run.+ 2 Nínú ọ̀rọ̀ yìí, ohun tí à ń retí lọ́dọ̀ àwọn ìríjú ni pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. 3 Lójú tèmi, kò jẹ́ nǹkan kan pé kí ẹ̀yin tàbí àwùjọ ìgbẹ́jọ́* téèyàn gbé kalẹ̀ wádìí mi wò. Kódà, èmi gan-an kò wádìí ara mi wò. 4 Nítorí mi ò rí nǹkan tó burú nínú ohun tí mo ṣe. Àmọ́, èyí kò túmọ̀ sí pé mo jẹ́ olódodo; ẹni tó ń wádìí mi wò ni Jèhófà.*+ 5 Nítorí náà, ẹ má ṣèdájọ́+ ohunkóhun ṣáájú àkókò tó yẹ, títí Olúwa yóò fi dé. Yóò mú àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ inú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀, á sì jẹ́ kí a mọ èrò ọkàn àwọn èèyàn, lẹ́yìn náà, kálukú á gba ìyìn rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+

6 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo ti fi èmi àti Àpólò+ ṣàpẹẹrẹ* àwọn nǹkan yìí fún ire yín, kó lè jẹ́ pé nípasẹ̀ wa, ẹ máa kọ́ ìlànà tó sọ pé: “Má ṣe kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀,” kí ẹ má bàa gbéra ga,+ tí ẹ ó sì máa sọ pé ẹnì kan dára ju èkejì lọ. 7 Nítorí ta ló mú ọ yàtọ̀ sí ẹlòmíràn? Ní tòótọ́, kí lo ní tí kì í ṣe pé o gbà á?+ Tó bá jẹ́ pé ńṣe lo gbà á lóòótọ́, kí ló dé tí ò ń fọ́nnu bíi pé kì í ṣe pé o gbà á?

8 Ṣé ó ti tẹ́ yín lọ́rùn báyìí? Ṣé ẹ ti lọ́rọ̀ báyìí? Ṣé ẹ ti ń ṣàkóso bí ọba+ láìsí àwa? Ì bá wù mí kí ẹ ti máa ṣàkóso bí ọba, kí àwa náà lè ṣàkóso pẹ̀lú yín bí ọba.+ 9 Nítorí lójú tèmi, ó dà bíi pé Ọlọ́run ti fi àwa àpọ́sítélì sí ìgbẹ̀yìn láti fi wá hàn bí àwọn tí a ti dájọ́ ikú fún,+ nítorí a ti di ìran àpéwò fún ayé+ àti fún àwọn áńgẹ́lì àti fún àwọn èèyàn. 10 Àwa jẹ́ òmùgọ̀+ nítorí Kristi, àmọ́ ẹ̀yin jẹ́ olóye nínú Kristi; àwa jẹ́ aláìlera, àmọ́ ẹ̀yin jẹ́ alágbára; ẹ̀yin ní iyì, àmọ́ àwa kò ní iyì. 11 Títí di wákàtí yìí, ebi ń pa wá,+ òùngbẹ ń gbẹ wá,+ a ò rí aṣọ tó dáa wọ̀,* wọ́n ń nà wá,*+ a ò sì rí ilé gbé, 12 à ń ṣe làálàá, a sì ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́.+ Nígbà tí wọ́n ń bú wa, à ń súre;+ nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, à ń fara dà á pẹ̀lú sùúrù;+ 13 nígbà tí wọ́n bà wá lórúkọ jẹ́, a fi ohùn pẹ̀lẹ́ dáhùn;*+ a ti dà bíi pàǹtírí* ayé, èérí ohun gbogbo, títí di báyìí.

14 Kì í ṣe kí n lè dójú tì yín ni mo ṣe ń kọ àwọn nǹkan yìí sí yín, àmọ́ kí n lè gbà yín níyànjú bí àwọn ọmọ mi tó jẹ́ àyànfẹ́. 15 Nítorí bí ẹ bá tiẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) atọ́nisọ́nà* nínú Kristi, ẹ kò ní baba púpọ̀; torí nínú Kristi Jésù, mo di baba yín nípasẹ̀ ìhìn rere.+ 16 Nítorí náà, mo rọ̀ yín, ẹ máa fara wé mi.+ 17 Ìdí nìyẹn tí mo fi rán Tímótì sí yín, torí ó jẹ́ ọmọ mi ọ̀wọ́n àti olóòótọ́ nínú Olúwa. Á rán yín létí àwọn ọ̀nà tí mò ń gbà ṣe nǹkan* ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù,+ bí mo ṣe ń kọ́ni níbi gbogbo nínú gbogbo ìjọ.

18 Àwọn kan ń gbéra ga, bíi pé mi ò ní wá sọ́dọ̀ yín. 19 Àmọ́ màá wá sọ́dọ̀ yín láìpẹ́, tí Jèhófà* bá fẹ́, kí n lè mọ agbára tí àwọn tó ń gbéra ga ní, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. 20 Nítorí Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe ti ọ̀rọ̀ ẹnu, ti agbára ni. 21 Èwo lẹ fẹ́? Ṣé kí n wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú ọ̀pá+ àbí kí n wá pẹ̀lú ìfẹ́ àti ẹ̀mí ìwà tútù?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́