December
Monday, December 1
‘A máa jí àwọn òkú dìde.’—Lúùkù 20:37.
Ṣé Jèhófà lágbára láti jí àwọn òkú dìde? Bẹ́ẹ̀ ni! Ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀ torí òun ni “Olódùmarè.” (Ìfi. 1:8) Ó lágbára láti ṣẹ́gun ọ̀tá èyíkéyìí títí kan ikú. (1 Kọ́r. 15:26) Ìdí míì tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run lágbára láti jí àwọn òkú dìde ni pé kì í gbàgbé nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, ó mọ orúkọ gbogbo àwọn ìràwọ̀. (Àìsá. 40:26) Bákan náà, Jèhófà ò gbàgbé àwọn tó ti kú. (Jóòbù 14:13; Lúùkù 20:38) Ó máa rántí kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn tó fẹ́ jí dìde títí kan bí wọ́n ṣe rí, ìwà wọn àtàwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn. A lè gba ìlérí tí Jèhófà ṣe gbọ́ pé òun máa jí àwọn òkú dìde lọ́jọ́ iwájú torí ó dá wa lójú pé ó wù ú, ó sì lágbára láti mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Ìdí míì tá a fi gbà pé Jèhófà máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ ni pé ó ti jí àwọn èèyàn dìde láwọn ìgbà kan. Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Jèhófà fún àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ kan lágbára láti jí òkú dìde, Jésù sì wà lára àwọn tó fún lágbára yìí. w23.04 9-10 ¶7-9
Tuesday, December 2
Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure, tí iyọ̀ dùn.—Kól. 4:6.
Tá a bá fọgbọ́n ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn gbọ́ wa, kí wọ́n sì fẹ́ ká máa bá ìjíròrò náà lọ. Àmọ́ ṣá o, tá a bá rí i pé ẹnì kan ń bá wa jiyàn tàbí pé ó ń ta ko ohun tá a gbà gbọ́, kò pọn dandan ká máa bá ìjíròrò náà lọ. (Òwe 26:4) Àmọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò wọ́pọ̀ torí ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa fetí sí wa. Torí náà tá a bá níwà tútù, ó máa ṣe wá láǹfààní. Táwọn èèyàn bá bi ẹ́ ní ìbéèrè tó le tàbí tí wọ́n ta kò ẹ́, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ lókun kó o lè dá wọn lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́. Máa rántí pé tó o bá dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́, ọ̀rọ̀ náà ò ní di àríyànjiyàn. Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá níwà tútù, tó o sì bọ̀wọ̀ fún wọn, ìdáhùn ẹ lè mú káwọn kan yí èrò tí wọ́n ní nípa Bíbélì àti nípa wa pa dà. Torí náà, ó yẹ ká “ṣe tán nígbà gbogbo láti gbèjà” ohun tá a gbà gbọ́, àmọ́ ká “máa fi ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.” (1 Pét. 3:15) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ìwà tútù máa fún wa lágbára! w23.09 19 ¶18-19
Wednesday, December 3
Ẹ fi . . . sùúrù wọ ara yín láṣọ.—Kól. 3:12.
Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan mẹ́rin tí ẹni tó ní sùúrù máa ń ṣe. Àkọ́kọ́, ẹni tó ní sùúrù kì í tètè bínú. Táwọn èèyàn bá múnú bí i, ó máa ń ní sùúrù, kì í sì í gbẹ̀san. (Ẹ́kís. 34:6) Ìkejì, ẹni tó ní sùúrù máa ń fi sùúrù dúró de nǹkan. Tí ẹni tó ní sùúrù bá ń dúró de nǹkan kan àmọ́ tí nǹkan náà ò tètè dé, kì í jẹ́ kí nǹkan tojú sú òun, kì í sì í kanra. (Mát. 18:26, 27) Ìkẹta, ẹni tó ní sùúrù kì í kánjú ṣe nǹkan. Tí ẹni tó ní sùúrù bá rí i pé ohun pàtàkì kan wà tóun gbọ́dọ̀ ṣe, kò ní kánjú bẹ̀rẹ̀ ẹ̀, kò sì ní máa kánjú kó lè tètè parí ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa rí i dájú pé òun fi àkókò tó pọ̀ tó ṣe nǹkan náà. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, á ṣe iṣẹ́ náà dáadáa. Ìkẹrin, ẹni tó ní sùúrù máa ń fara da ìṣòro láì ráhùn. Ó máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti fara da ìṣòro, kó sì máa láyọ̀. (Kól. 1:11) Torí náà, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ máa ní sùúrù láwọn ipò tá a sọ yìí. w23.08 20-21 ¶3-6
Thursday, December 4
Jèhófà ni olùṣàyẹ̀wò ọkàn.—Òwe 17:3.
Ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa kíyè sí ohun tó wà lọ́kàn wa ni pé Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn. Ìyẹn ni pé arínúróde ni Jèhófà, ó sì mọ̀ wá ju báwọn èèyàn ṣe mọ̀ wá lọ. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Jèhófà ń fún wa, ó máa nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa jẹ́ ká wà láàyè títí láé. (Jòh. 4:14) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní ṣèṣekúṣe, a ò sì ní hùwà ìbàjẹ́ tí Sátánì àtàwọn èèyàn ayé ń fẹ́. (1 Jòh. 5:18, 19) Bá a bá ṣe ń sún mọ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, tí àá sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Torí pé a ò fẹ́ ṣe ohun tó máa dun Baba wa ọ̀run, a ò ní máa ro èròkerò tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀. Ìgbà kan wà tó máa ń ṣe Arábìnrin Marta tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Croatia bíi pé kó ṣèṣekúṣe, ó sọ pé: “Ó máa ń wù mí láti ṣèṣekúṣe, kò sì rọrùn fún mi láti borí èrò burúkú yìí. Àmọ́ torí pé mo bẹ̀rù Jèhófà, mi ò ṣèṣekúṣe.” Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe ran Arábìnrin Marta lọ́wọ́? Ó sọ pé òun máa ń ronú lórí ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí torí òun mọ̀ pé ìgbẹ̀yìn ẹ̀ ò ní dáa. Bó ṣe yẹ káwa náà máa ronú nìyẹn. w23.06 20-21 ¶3-4
Friday, December 5
“Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, “nígbà tí mo bá fi hàn lójú wọn pé mo jẹ́ mímọ́ láàárín yín.”—Ìsík. 36:23.
Jésù mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí orúkọ ẹ̀ di mímọ́, kó sì mú gbogbo ẹ̀gàn kúrò lára orúkọ náà. Ìdí nìyẹn tí Jésù Ọ̀gá wa fi kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́.” (Mát. 6:9) Jésù mọ̀ pé ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù lójú gbogbo èèyàn ni bí wọ́n ṣe máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Láyé àtọ̀run, kò sẹ́ni tó sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ tó Jésù. Àmọ́ nígbà tí wọ́n fàṣẹ ọba mú Jésù, ẹ̀sùn wo làwọn ọ̀tá ẹ̀ fi kàn án? Wọ́n ní ó tàbùkù sí Ọlọ́run! Jésù mọ̀ dájú pé kéèyàn ba orúkọ Bàbá ẹ̀ mímọ́ jẹ́ ni ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jù lọ. Ó dùn ún gan-an pé ẹ̀sùn burúkú yìí ni wọ́n fi kan òun tí wọ́n sì sọ pé òun jẹ̀bi. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyẹn ló mú kí “ìdààmú bá a gan-an” nígbà tí wọ́n fẹ́ mú un.—Lúùkù 22:41-44. w24.02 11 ¶11
Saturday, December 6
Ọgbọ́n la fi ń gbé ilé ró.—Òwe 24:3.
Bá a ṣe ń sáré ìyè, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù ju àwọn mọ̀lẹ́bí wa lọ. (Mát. 10:37) Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ká pa ojúṣe wa nínú ìdílé tì torí ojúṣe ìdílé wa ò sọ pé ká má ṣohun tí Ọlọ́run àti Kristi fẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, tá a bá fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run àti Kristi fẹ́, a gbọ́dọ̀ ṣe ojúṣe wa nínú ìdílé. (1 Tím. 5:4, 8) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa láyọ̀. Jèhófà mọ̀ pé ìdílé máa láyọ̀ tí ọkọ àti ìyàwó bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Bákan náà, ìdílé á láyọ̀ táwọn òbí bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n tọ́ wọn lọ́nà tó tọ́, táwọn ọmọ náà sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. (Éfé. 5:33; 6:1, 4) Bóyá ọkọ, aya tàbí ọmọ ni ẹ́, ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ni kó o máa lò, dípò tí wàá fi gbára lé èrò tara ẹ, àṣà ìbílẹ̀ ẹ tàbí ohun táwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ agbaninímọ̀ràn sọ. Máa kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Nínú àwọn ìwé náà, wàá rí àwọn àbá tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ táá jẹ́ kó o máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. w23.08 28 ¶6-7
Sunday, December 7
Máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà á tọ̀sántòru, kí o lè rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀; ìgbà yẹn ni ọ̀nà rẹ máa yọrí sí rere, tí wàá sì máa hùwà ọgbọ́n.—Jóṣ. 1:8.
Ó yẹ kí obìnrin Kristẹni kan kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe é láǹfààní. Àwọn nǹkan tí ọmọbìnrin kan bá kọ́ nígbà tó wà ní kékeré máa ràn án lọ́wọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, kọ́ bó o ṣe lè mọ̀wé kọ, kó o sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa. Láwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, wọ́n gbà pé kò pọn dandan kí obìnrin kọ́ bó ṣe lè mọ̀wé kọ, kó sì mọ̀ ọ́n kà. Àmọ́, gbogbo àwa Kristẹni ló yẹ ká mọ̀wé kọ, ká sì mọ̀ ọ́n kà. (1 Tím. 4:13) Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti kọ́ bó o ṣe lè mọ̀wé kọ, kó o sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa. Àǹfààní wo lo máa rí? Á jẹ́ kó o ríṣẹ́ tí wàá fi máa gbọ́ bùkátà ara ẹ, tí ò sì ní bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Á jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á sì jẹ́ kíwọ náà di olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́. Àmọ́ àǹfààní tó dáa jù tó o máa rí bó o ṣe ń ka Bíbélì, tó o sì ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀ ni pé á jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.—1 Tím. 4:15. w23.12 20 ¶10-11
Monday, December 8
Jèhófà mọ bó ṣe ń gba àwọn èèyàn tó ń sìn ín tọkàntọkàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àdánwò.—2 Pét. 2:9.
Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí ìdẹwò. Torí pé aláìpé ni wá, gbogbo ìgbà la máa ń sapá ká má bàa kó sínú ìdẹwò tàbí ṣe ohun tí ò dáa. Sátánì máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe ká má bàa ṣàṣeyọrí. Ọ̀nà kan tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ ká máa wo eré oníṣekúṣe. Irú eré ìnàjú bẹ́ẹ̀ lè mú ká máa ro èròkerò, ó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ó sì lè mú ká dẹ́ṣẹ̀ ńlá. (Máàkù 7:21-23; Jém. 1:14, 15) Ká tó lè borí ìdẹwò, àfi kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà, ó ní kí wọ́n máa bẹ Jèhófà pé: ‘Má mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.’ (Mát. 6:13) Jèhófà fẹ́ ràn wá lọ́wọ́, àmọ́ ó yẹ ká sọ fún un pé kó ràn wá lọ́wọ́. Lẹ́yìn tá a ti gbàdúrà pé kó ràn wá lọ́wọ́, àwa náà gbọ́dọ̀ máa sá fún ohun tó lè dẹ wá wò. w23.05 6-7 ¶15-17
Tuesday, December 9
Okùn onífọ́nrán mẹ́ta kò ṣeé tètè fà já.—Oníw. 4:12.
Tí tọkọtaya kan bá mọyì àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà, á rọrùn fún wọn láti máa fi ìmọ̀ràn ẹ̀ sílò, wọn ò ní máa ṣe ohun táá fa ìṣòro, tí ìṣòro bá sì dé, wọ́n á ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti borí ẹ̀ kí ìfẹ́ wọn má bàa di tútù. Ó yẹ káwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn náà sapá láti fara wé Jèhófà, kí wọ́n láwọn ìwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní bí inúure àti sùúrù, kí wọ́n sì máa dárí ji ara wọn. (Éfé. 4:32–5:1) Ó máa rọrùn fáwọn tọkọtaya tó bá ní àwọn ànímọ́ yìí láti fìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn síra wọn. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lena, tó sì ti ṣègbéyàwó ní ohun tó lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) sọ pé: “Ó máa ń rọrùn láti nífẹ̀ẹ́ ẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, kéèyàn sì bọ̀wọ̀ fún un.” Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì. Nígbà tí Jèhófà fẹ́ yan àwọn tó máa bí Mèsáyà, Jósẹ́fù àti Màríà ni Jèhófà yàn láàárín àwọn àtọmọdọ́mọ Dáfídì. Kí nìdí? Àwọn méjèèjì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, Jèhófà sì mọ̀ pé ìfẹ́ tí wọ́n ní sí òun máa mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn túbọ̀ lágbára. w23.05 20-21 ¶3-4
Wednesday, December 10
Ẹ máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín.—Héb. 13:17.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù Aṣáájú wa, àwọn tó ń lò láti ṣàbójútó wa kì í ṣe ẹni pípé. Ó lè má rọrùn fún wa láti ṣe ohun tí wọ́n sọ, pàápàá tóhun tí wọ́n ní ká ṣe ò bá wù wá. Ìgbà kan wà tí kò rọrùn fún àpọ́sítélì Pétérù láti ṣègbọràn. Nígbà tí áńgẹ́lì kan ní kó jẹ àwọn ẹran tí Òfin Mósè kà léèwọ̀, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù kọ̀ jálẹ̀! (Ìṣe 10:9-16) Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tí áńgẹ́lì náà ní kó ṣe ò bọ́gbọ́n mu lójú ẹ̀. Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní tiẹ̀ ṣègbọràn nígbà táwọn àgbààgbà ọkùnrin Jerúsálẹ́mù sọ fún un pé kó mú ọkùnrin mẹ́rin lọ sínú tẹ́ńpìlì kó sì wẹ ara ẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn, kó lè fi hàn pé òun ń pa Òfin Mósè mọ́. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àwọn Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò jẹ̀bi, ó “mú àwọn ọkùnrin náà dání ní ọjọ́ kejì, ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn lọ́nà Òfin.” (Ìṣe 21:23, 24, 26) Ẹ ò rí i pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe yẹn mú kí àlàáfíà wà láàárín àwọn ará.—Róòmù 14:19, 21. w23.10 10 ¶15-16
Thursday, December 11
Àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.—Sm. 25:14.
Ó dájú pé o ò ní ronú pé àwọn méjì kan gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù ara wọn kí wọ́n tó di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Àmọ́, àwọn tó bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Jèhófà tímọ́tímọ́ gbọ́dọ̀ máa “bẹ̀rù” rẹ̀. Bóyá ó ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà tàbí kò tíì pẹ́, gbogbo wa ló yẹ ká máa bẹ̀rù Jèhófà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àmọ́ kí ló ń fi hàn pé ẹnì kan bẹ̀rù Ọlọ́run? Kí lá jẹ́ ká máa bẹ̀rù Jèhófà? Ẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an, kò sì ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa ba àjọṣe àárín wọn jẹ́. Irú “ìbẹ̀rù Ọlọ́run” yìí ni Jésù ní. (Héb. 5:7) Kì í gbọ̀n jìnnìjìnnì torí Jèhófà. (Àìsá. 11:2, 3) Dípò bẹ́ẹ̀, ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu. (Jòh. 14:21, 31) Torí náà bíi ti Jésù, àwa náà ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, a sì bẹ̀rù ẹ̀ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó gbọ́n, onídàájọ́ òdodo ni, ó sì lágbára. A mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, inú ẹ̀ sì máa ń dùn tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà ẹ̀. Torí náà, tá a bá ṣàìgbọràn sí Jèhófà, inú ẹ̀ ò ní dùn, àmọ́ tá a bá ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu, inú ẹ̀ máa dùn.—Sm. 78:41; Òwe 27:11. w23.06 14 ¶1-2; 15 ¶5
Friday, December 12
Bó ṣe di alágbára tán, ìgbéraga wọ̀ ọ́ lẹ́wù débi tó fi fa àjálù bá ara rẹ̀, ó sì hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà.—2 Kíró. 26:16.
Nígbà tí Ùsáyà di alágbára, ó gbàgbé pé Jèhófà ló jẹ́ kóun ṣe gbogbo àṣeyọrí tóun ṣe. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà ló fún wa ní gbogbo ohun rere tá a ní, òun ló sì ń bù kún wa. Dípò ká máa fi àwọn àṣeyọrí wa yangàn, Jèhófà ló yẹ ká gbé gbogbo ògo náà fún. (1 Kọ́r. 4:7) Ó yẹ ká gbà pé aláìpé ni wá, ká sì máa fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí tí wọ́n bá fún wa. Arákùnrin kan tó ti lé lẹ́ni ọgọ́ta (60) ọdún sọ pé: “Mi kì í ro ara mi ju bó ṣe yẹ lọ. Tí wọ́n bá bá mi wí torí àṣìṣe tí mo ṣe, mo máa ń fìrẹ̀lẹ̀ gbà á, mo sì máa ń ṣàtúnṣe.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé tá a bá bẹ̀rù Jèhófà tá a sì nírẹ̀lẹ̀, ìgbésí ayé wa máa dáa, àá sì láyọ̀.—Òwe 22:4. w23.09 10 ¶10-11
Saturday, December 13
Ẹ nílò ìfaradà, pé lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ lè rí ohun tí ó ṣèlérí náà gbà.—Héb. 10:36.
Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ gba pé kí wọ́n nífaradà. Wọ́n láwọn ìṣòro tó ń bá gbogbo èèyàn fínra nígbà yẹn, wọ́n tún láwọn ìṣòro míì torí pé Kristẹni ni wọ́n. Ọ̀pọ̀ lára wọn làwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù àtàwọn aláṣẹ Róòmù ṣenúnibíni sí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn náà tún ṣenúnibíni sí wọn. (Mát. 10:21) Bákan náà láwọn ìgbà míì, wọ́n tún gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn ò jẹ́ kí ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà fa ìpínyà nínú ìjọ. (Ìṣe 20:29, 30) Síbẹ̀, àwọn Kristẹni yẹn fara dà á. (Ìfi. 2:3) Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? Wọ́n ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Ìwé Mímọ́, irú bíi ti Jóòbù. (Jém. 5:10, 11) Wọ́n tún gbàdúrà pé kí Jèhófà fún àwọn lókun. (Ìṣe 4:29-31) Wọ́n sì fi sọ́kàn pé Jèhófà máa bù kún àwọn táwọn bá fara dà á. (Ìṣe 5:41) Àwa náà lè fara dà á tá a bá ń kà nípa àwọn tó fara da ìṣòro nínú Bíbélì àtàwọn ìwé wa, tá a sì ń ronú lórí wọn. w23.07 3 ¶5-6
Sunday, December 14
Torí náà, ẹ máa wá Ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn yìí la sì máa fi kún un fún yín.—Mát. 6:33.
Jèhófà àti Jésù ò ní pa wá tì. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù rí, ó gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu pàtàkì kan nígbèésí ayé ẹ̀. Ṣé ó máa lóun ò wàásù mọ́ àbí á ṣì máa wàásù nípa Kristi nìṣó? Jésù ti gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí ìgbàgbọ́ Pétérù túbọ̀ lágbára. Jésù sọ fún Pétérù nípa àdúrà yẹn, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun fọkàn tán an pé tó bá yá, ó máa fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lókun. (Lúùkù 22:31, 32) Ẹ ò rí i pé tí Pétérù bá rántí ohun tí Jésù sọ yìí, ó máa fún un níṣìírí gan-an! Táwa náà bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì nígbèésí ayé wa, Jèhófà lè lo àwọn alábòójútó tó nífẹ̀ẹ́ wa láti tọ́ wa sọ́nà, ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Éfé. 4:8, 11) Bí Jèhófà ṣe pèsè àwọn nǹkan tí Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù nílò, ó máa pèsè fáwa náà tá a bá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù nígbèésí ayé wa. w23.09 24-25 ¶14-15
Monday, December 15
Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan, á sì san án pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.—Òwe 19:17.
Ohun tá a bá ṣe máa ń ṣeyebíye lójú Jèhófà, ó sì máa ń wò ó bíi gbèsè tóun máa san pa dà fún wa. Tó o bá ti ṣiṣẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ rí, Jèhófà ò gbàgbé iṣẹ́ tó o ṣe nígbà yẹn àti ìfẹ́ tó mú kó o ṣiṣẹ́ náà. (1 Kọ́r. 15:58) Bákan náà, ó ṣì ń kíyè sí bó o ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará. Jèhófà fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ òun àtàwọn èèyàn. Tá a bá ń ka Bíbélì, tá à ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, tá a sì ń gbàdúrà déédéé, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á túbọ̀ lágbára. Bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ni pé ká máa ṣe àwọn nǹkan tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí ìfẹ́ tá a ní bá ṣe ń lágbára sí i, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àtàwọn ará, àá sì jọ máa ṣọ̀rẹ́ títí láé. w23.07 10 ¶11; 11 ¶13; 13 ¶18
Tuesday, December 16
Kálukú ló máa ru ẹrù ara rẹ̀.—Gál. 6:5.
Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu irú ìtọ́jú tóun máa gbà. Àmọ́ àwọn òfin kan wà nínú Bíbélì táwa Kristẹni gbọ́dọ̀ pa mọ́ tá a bá fẹ́ gbàtọ́jú. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé ká ta kété sí ẹ̀jẹ̀ àti ìbẹ́mìílò. (Ìṣe 15:20; Gál. 5:19, 20) Yàtọ̀ sáwọn òfin tí Bíbélì sọ yẹn, Kristẹni kan lè pinnu irú ìtọ́jú tóun máa gbà. Tá a bá tiẹ̀ rò pé irú ìtọ́jú tá a mọ̀ ló dáa jù, ó yẹ ká fi àwọn ará wa lọ́rùn sílẹ̀, kí wọ́n pinnu irú ìtọ́jú tí wọ́n máa gbà. Torí náà, kò yẹ ká gbàgbé àwọn nǹkan pàtàkì yìí: (1) Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú àìsàn kúrò pátápátá. (Àìsá. 33:24) (2) Ó gbọ́dọ̀ ‘dá Kristẹni kọ̀ọ̀kan lójú hán-ún hán-ún’ pé ìtọ́jú tóun fẹ́ gbà ló dáa jù fóun. (Róòmù 14:5) (3) A ò gbọ́dọ̀ dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ nítorí ìpinnu tí wọ́n ṣe tàbí ká ṣe ohun tó máa mú kí wọ́n kọṣẹ̀. (Róòmù 14:13) (4) Àwa Kristẹni máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, tá ò bá jẹ́ kí òmìnira tá a ní láti yan ohun tó wù wá ba àlàáfíà ìjọ jẹ́.—Róòmù 14:15, 19, 20. w23.07 24 ¶15
Wednesday, December 17
Ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi jẹ́ Násírì, ó jẹ́ mímọ́ sí Jèhófà.—Nọ́ń. 6:8.
Ṣé o mọyì àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà? Ó dájú pé o ṣe bẹ́ẹ̀! Bákan náà nígbà àtijọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló mọyì àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú ẹ̀. (Sm. 104:33, 34) Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà la máa ń yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan ká lè jọ́sìn ẹ̀. Ohun táwọn Násírì tàbí àwọn tí a yà sí mímọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe nìyẹn. Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí báwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣe yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n lè sin Jèhófà lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Òfin Mósè gba ọkùnrin tàbí obìnrin kan láyè láti jẹ́jẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún Jèhófà pé òun máa di Násírì fún àkókò kan. (Nọ́ń. 6:1, 2) Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá jẹ́jẹ̀ẹ́ láti di Násírì, á máa pa àwọn òfin kan mọ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù kì í pa mọ́. Àmọ́, kí ló máa ń jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan jẹ́jẹ̀ẹ́ láti di Násírì? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìfẹ́ tí irú ọmọ Ísírẹ́lì bẹ́ẹ̀ ní sí Jèhófà àti bó ṣe mọyì ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jèhófà ṣe fún un ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀.—Diu. 6:5; 16:17. w24.02 14 ¶1-2
Thursday, December 18
Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.—Dán. 9:4.
Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ Hébérù náà “adúróṣinṣin” tàbí “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀” tó bá ń sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ olóòótọ́ sáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí kan náà la máa ń lò tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa báwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (2 Sám. 9:6, 7) Àmọ́, ká tó lè jẹ́ adúróṣinṣin, ó máa gba àkókò. Ẹ jẹ́ ká wo bí Dáníẹ́lì ṣe túbọ̀ fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ sí Dáníẹ́lì tó gba pé kó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Àmọ́, ó ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún (90) ọdún nígbà tí àdánwò tó le jù dé bá a. Àwọn ìjòyè ọba kórìíra Dáníẹ́lì gan-an, wọn ò sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run tó ń sìn. Torí náà, wọ́n wá bí wọ́n ṣe máa fẹ̀sùn kan Dáníẹ́lì kí wọ́n lè pa á. Wọ́n ṣe òfin kan tí ọba fọwọ́ sí tó máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá Ọlọ́run tí Dáníẹ́lì ń sìn ló máa jẹ́ adúróṣinṣin sí àbí ọba. Ohun tí Dáníẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kó lè fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọba Dáríúsì ni pé kò gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí Jèhófà fún ọgbọ̀n (30) ọjọ́. Dípò kí Dáníẹ́lì ṣe ohun tí wọ́n sọ, Jèhófà ló jẹ́ adúróṣinṣin sí.—Dán. 6:12-15, 20-22. w23.08 5 ¶10-12
Friday, December 19
Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa.—1 Jòh. 4:7
Jèhófà fẹ́ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nígbà gbogbo. Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣohun tí ò dáa sí wa, ó yẹ ká gbà pé kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣohun tó ṣe yẹn torí pé ó máa ń wù ú pé kó ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Òwe 12:18) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ láìka kùdìẹ̀-kudiẹ wọn sí. Tá a bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe tàbí tá a ṣe ohun tó dùn ún, kì í torí ìyẹn pa wá tì tàbí kó bínú sí wa. (Sm. 103:9) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fara wé Jèhófà, Bàbá wa tó máa ń dárí jini! (Éfé. 4:32–5:1) Ó yẹ ká máa rántí pé bí òpin ṣe ń sún mọ́lé, ó ṣe pàtàkì ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará wa. Ó tún yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn èèyàn máa ṣenúnibíni tó le gan-an sí wa. Wọ́n tiẹ̀ lè fi wá sẹ́wọ̀n torí ohun tá a gbà gbọ́. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, àsìkò yẹn gan-an la máa túbọ̀ mọyì àwọn ará wa ju ti ìgbàkigbà rí lọ.—Òwe 17:17. w24.03 15-16 ¶6-7
Saturday, December 20
Jèhófà ló ń darí ìṣísẹ̀ èèyàn.—Òwe 20:24.
Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n sún mọ́ Jèhófà, tí wọ́n rí ojúure ẹ̀, tí wọ́n sì láyọ̀. Ọ̀kan lára wọn ni Dáfídì. Àtikékeré ló ti pinnu pé Ọlọ́run lòun máa sìn, nígbà tó sì yá, ó di ọba tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (1 Ọba 3:6; 9:4, 5; 14:8) Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Dáfídì ṣe jẹ́ olóòótọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀, ó lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. O tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Máàkù tàbí Tímótì. Àtikékeré ni wọ́n ti ń sin Jèhófà, wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí i, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Àwọn nǹkan tó o bá ń fayé ẹ ṣe báyìí ló máa sọ bí ìgbésí ayé ẹ ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tó ò sì gbára lé òye tara ẹ, wàá ṣe ìpinnu tó dáa. Ká sòótọ́, o lè gbé ìgbé ayé táá jẹ́ kó o láyọ̀. Rántí pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe fún un. Torí náà, kò sóhun tó dáa tó kó o fayé ẹ sin Jèhófà Bàbá wa ọ̀run. w23.09 13 ¶18-19
Sunday, December 21
Ẹ máa . . . dárí ji ara yín fàlàlà.—Kól. 3:13.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé aláìpé làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin òun. Bí àpẹẹrẹ, kò pẹ́ sígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìjọ táwọn kan fi ń bẹ̀rù ẹ̀ torí wọn ò gbà pé ó ti di ọmọlẹ́yìn Jésù. (Ìṣe 9:26) Nígbà tó yá, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa lẹ́yìn. (2 Kọ́r. 10:10) Pọ́ọ̀lù tún rí alàgbà kan tó ṣe ìpinnu tó lè mú káwọn míì kọsẹ̀. (Gál. 2:11, 12) Yàtọ̀ síyẹn, Máàkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ já a kulẹ̀. (Ìṣe 15:37, 38) Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù yìí lè mú kó máa yẹra fáwọn tó ṣẹ̀ ẹ́. Síbẹ̀, ojú tó dáa ló fi ń wo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ̀, ó sì ń sin Jèhófà nìṣó. Kí ló jẹ́ kó lè fara dà á? Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ̀. Ìfẹ́ tó ní sí wọn yìí ni ò jẹ́ kó máa wo ibi tí wọ́n kù sí, ibi tí wọ́n dáa sí nìkan ló máa ń wò. Ó dájú pé ìfẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ní yìí ló mú kó lè ṣohun tí ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní sọ. w24.03 15 ¶4-5
Monday, December 22
Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, àmọ́ ó yẹ kó máa hùwà jẹ́jẹ́ sí gbogbo èèyàn.—2 Tím. 2:24.
Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká rí i pé ìwà tútù máa ń ṣeni láǹfààní. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ísákì. Nígbà tó pàgọ́ sí agbègbè Gérárì ní Filísínì, àwọn Filísínì tó wà lágbègbè yẹn jowú ẹ̀, wọ́n sì dí àwọn kànga tí bàbá ẹ̀ gbẹ́ pa. Dípò kí Ísákì bá wọn jà, ńṣe ló kó àwọn ará ilé ẹ̀ kúrò lágbègbè yẹn lọ sí agbègbè míì tó jìnnà, ó sì gbẹ́ àwọn kànga míì síbẹ̀. (Jẹ́n. 26:12-18) Síbẹ̀, ṣe làwọn Filísínì tún sọ pé àwọn làwọn ni omi inú àwọn kànga náà. Láìka gbogbo èyí sí, Ísákì ò bá wọn jà. (Jẹ́n. 26:19-25) Kí ló jẹ́ kó níwà tútù bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn yẹn fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ múnú bí i? Ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni pé ó ti kẹ́kọ̀ọ́ lára Ábúráhámù bàbá ẹ̀ tó máa ń wá àlàáfíà àti Sérà ìyá ẹ̀ tó ní “ìwà jẹ́jẹ́ àti ìwà tútù.”—1 Pét. 3:4-6; Jẹ́n. 21:22-34. w23.09 15 ¶4
Tuesday, December 23
Mo ti ní in lọ́kàn, màá sì ṣe é.—Àìsá. 46:11.
Jèhófà rán àkọ́bí Ọmọ ẹ̀ wá sáyé kó lè kọ́ wa nípa Ìjọba náà, kó sì fi ẹ̀mí ẹ̀ rà wá pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Lẹ́yìn náà, Jèhófà jí Jésù dìde pa dà sí ọ̀run kó lè di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ohun tí Bíbélì dá lé ni bí Jèhófà ṣe máa dá orúkọ ẹ̀ láre, tó sì máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ tí Kristi máa ṣàkóso. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe ò lè yí pa dà láé. Ó ti fi dá wa lójú pé òun máa ṣe é láṣeyọrí. (Àìsá. 46:10, àlàyé ìsàlẹ̀; Héb. 6:17, 18) Tó bá yá, Jèhófà máa sọ ayé yìí di Párádísè níbi táwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tó ti di pípé, tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ ti máa “gbádùn ayé títí láé.” (Sm. 22:26) Àmọ́ ohun tí Jèhófà máa ṣe jùyẹn lọ. Ohun tó wù ú jù ni bó ṣe máa mú kí gbogbo àwọn tó dá sọ́run àti ayé máa jọ́sìn ẹ̀ níṣọ̀kan. Tó bá dìgbà yẹn, gbogbo àwọn tó wà láàyè ló máa gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. (Éfé. 1:8-11) Ṣé kò yà ẹ́ lẹ́nu bó o ṣe ń rí àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe kó lè mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ? w23.10 20 ¶7-8
Wednesday, December 24
‘Ẹ jẹ́ onígboyà, torí mo wà pẹ̀lú yín,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.—Hág. 2:4.
Nígbà táwọn Júù tó kúrò ní Bábílónì dé Jerúsálẹ́mù, kò pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í níṣòro àtijẹ àtimu, àwọn èèyàn tí ìjọba Páṣíà ń ṣàkóso ń bá ara wọn jà, àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká wọn sì ń ta kò wọ́n. Ìyẹn jẹ́ kó ṣòro fáwọn kan lára wọn láti gbájú mọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà tí wọ́n ń tún kọ́. Torí náà, Jèhófà rán wòlíì Hágáì àti Sekaráyà pé kí wọ́n lọ fún wọn lókun, kí wọ́n lè máa fìtara ṣiṣẹ́ Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá wọn sọ sì fún wọn níṣìírí gan-an. (Hág. 1:1; Sek. 1:1) Àmọ́ ní nǹkan bí àádọ́ta (50) ọdún lẹ́yìn náà, àwọn Júù yẹn rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n sì ń fẹ́ ìṣírí. Ẹ́sírà akọ̀wé Òfin Ọlọ́run tó jáfáfá wá sí Jerúsálẹ́mù láti Bábílónì kó lè fún àwọn Júù yẹn níṣìírí, kí wọ́n lè gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. (Ẹ́sírà 7:1, 6) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Hágáì àti Sekaráyà sọ ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ nígbà àtijọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń ta kò wọ́n, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì lè ràn wá lọ́wọ́ lónìí láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á gbà wá nígbà ìṣòro.—Òwe 22:19. w23.11 14-15 ¶2-3
Thursday, December 25
Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.—Kól. 3:14.
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà? Ọ̀nà kan tá à ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a máa ń tù wọ́n nínú. Tá a bá lójú àánú, àá ‘máa tu ara wa nínú.’ (1 Tẹs. 4:18) Báwo la ṣe lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí ara wa? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti dárí ji àwọn ará, kódà tó bá nira fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará lásìkò tá a wà yìí? Kíyè sí ohun tí Pétérù sọ, ó ní: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. Torí náà, . . . ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara yín.” (1 Pét. 4:7, 8) Bí òpin ayé burúkú yìí ṣe ń sún mọ́lé, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí wa? Nígbà tí Jésù ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀, ó ní: “Gbogbo orílẹ̀-èdè sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.” (Mát. 24:9) Ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ká sì fara da ìkórìíra náà, a gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo ìsapá Sátánì máa já sásán, kò sì ní lè dá ìyapa sáàárín wa torí pé ìfẹ́ ló so wá pọ̀.— Fílí. 2:1, 2. w23.11 13 ¶18-19
Friday, December 26
Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá.—1 Kọ́r. 3:9.
Òtítọ́ lọ̀rọ̀ inú Bíbélì, ó sì lágbára gan-an. Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà àti irú ẹni tó jẹ́, ohun tí wọ́n mọ̀ nípa ẹ̀ ń yà wọ́n lẹ́nu. Ohun tí wọ́n ń kọ́ yẹn jẹ́ kí wọ́n rí i pé irọ́ ni Sátánì ń pa, wọ́n wá mọ̀ pé Jèhófà láwọn ànímọ́ tó dáa. Ẹnu yà wọ́n gan-an nítorí agbára ẹ̀ tí ò láàlà. (Àìsá. 40:26) Ohun tí wọ́n kọ́ jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́kẹ̀ lé e torí wọ́n rí i pé onídàájọ́ òdodo ni. (Diu. 32:4) Wọ́n tún kẹ́kọ̀ọ́ pé òun ló gbọ́n jù. (Àìsá. 55:9; Róòmù 11:33) Ara tù wọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. (1 Jòh. 4:8) Bí wọ́n ṣe ń mọ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ ló ń dá wọn lójú pé àwọn máa wà láàyè títí láé. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run! Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa pè wá ní “alábàáṣiṣẹ́” òun.—1 Kọ́r. 3:5. w24.02 12 ¶15
Saturday, December 27
Ó sàn kí o má ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ ju pé kí o jẹ́jẹ̀ẹ́, kí o má sì san án.—Oníw. 5:5.
Tó bá jẹ́ pé o ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí táwọn òbí ẹ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣé ó ń wù ẹ́ pé kó o ṣèrìbọmi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ohun tó dáa lo fẹ́ ṣe yẹn! Àmọ́ kó o tó lè ṣèrìbọmi, o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Báwo lo ṣe máa ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà? O máa ṣèlérí fún un nínú àdúrà pé òun nìkan ni wàá máa sìn àti pé bó o ṣe máa ṣe ìfẹ́ ẹ̀ lá ṣe pàtàkì jù sí ẹ. Ńṣe lo máa ṣèlérí fún un pé wàá nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ pẹ̀lú “gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30) Tó o bá fẹ́ ya ara ẹ sí mímọ́, kò sẹ́nì kankan tó máa mọ̀ torí àárín ìwọ àti Jèhófà nìkan lọ̀rọ̀ náà wà. Àmọ́ ojú ọ̀pọ̀ èèyàn lo ti máa ṣèrìbọmi, ìyẹn sì máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ti ya ara ẹ sí mímọ́. Ẹ̀jẹ́ tó o jẹ́ nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ ṣe pàtàkì gan-an, torí náà Jèhófà fẹ́ kó o mú ẹ̀jẹ́ yẹn ṣẹ, ó sì dájú pé ohun tíwọ fúnra ẹ náà fẹ́ ṣe nìyẹn.—Oníw. 5:4. w24.03 2 ¶2; 3 ¶5
Sunday, December 28
Kálukú yín gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; bákan náà, kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.—Éfé. 5:33.
Kò sí ìgbéyàwó tí ò níṣòro tiẹ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé bó ṣe rí nìyẹn nígbà tó sọ pé àwọn tó ṣègbéyàwó máa ní “ìpọ́njú nínú ara wọn.” (1 Kọ́r. 7:28) Kí nìdí? Ìdí ni pé aláìpé làwọn méjèèjì, ìwà wọn yàtọ̀ síra, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì lohun tí kálukú wọn nífẹ̀ẹ́ sí. Yàtọ̀ síyẹn, ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá, àṣà wọn sì yàtọ̀ síra. Tó bá yá, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn ìwà tí wọn ò mọ̀ pé ọkọ tàbí aya wọn ní kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. Tí wọn ò bá sì ṣọ́ra, ìyẹn lè fa ìṣòro. Dípò kí wọ́n máa di ẹ̀bi ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ru ọkọ tàbí aya wọn, ńṣe ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gbà pé òun jẹ̀bi lọ́nà kan, kí wọ́n sì wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ìṣòro náà. Wọ́n tiẹ̀ lè máa wò ó pé ohun tó máa yanjú ìṣòro náà ni pé káwọn pínyà tàbí kọ ara wọn sílẹ̀. Àmọ́ ṣéyẹn máa yanjú ìṣòro náà? Rárá o. Jèhófà ò fẹ́ kí tọkọtaya kọ ara wọn sílẹ̀ kódà tí ìwà ọkọ tàbí aya yẹn bá burú. w24.03 16 ¶8; 17 ¶11
Monday, December 29
Ìrètí kì í yọrí sí ìjákulẹ̀.—Róòmù 5:5.
Lẹ́yìn tó o ya ara ẹ sí mímọ́, tó o sì ṣèrìbọmi, o túbọ̀ mọ Jèhófà, o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, ó sì túbọ̀ dá ẹ lójú pé o máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè. (Héb. 5:13–6:1) Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Róòmù 5:2-4 sọ ti ṣẹlẹ̀ síwọ náà. Nígbà tó o níṣòro, tó o sì fara dà á, o rí bí inú Jèhófà ṣe dùn sí ẹ. Torí pé o rí i pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó túbọ̀ dá ẹ lójú pé wàá rí àwọn nǹkan tó ò ń retí gbà. Ìrètí tó o ní ti wá lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì dá ẹ lójú gan-an. Kódà, ó hàn nínú gbogbo nǹkan tó ò ń ṣe, bó o ṣe ń hùwà sí ìdílé ẹ, bó o ṣe ń ṣe ìpinnu àti bó o ṣe ń lo àkókò ẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún sọ nǹkan pàtàkì míì nípa ìrètí tó o ní lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gbà ẹ́. Ó jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ohun tó ò ń retí máa dé.—Róòmù 15:13. w23.12 12-13 ¶16-19
Tuesday, December 30
[Jèhófà] ló ń mú kí nǹkan lọ bó ṣe yẹ láwọn àkókò rẹ.—Àìsá. 33:6.
Tá a bá níṣòro tó le gan-an, bí nǹkan ṣe rí lára wa àti bá a ṣe ń ronú lè yàtọ̀ sí bá a ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀. Bí atẹ́gùn ṣe máa ń bi ọkọ̀ ojú omi síbí sọ́hùn-ún, bẹ́ẹ̀ náà ni ìṣòro ṣe lè jẹ́ ká ṣinú rò. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ tí ìṣòro wa bá ti ń kọjá ohun tá a lè fara dà? Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa fi wá lọ́kàn balẹ̀. Tí ìjì bá ń bì lu ọkọ̀ òkun kan, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í fì síbí fì sọ́hùn-ún, ìyẹn sì léwu gan-an. Kí ọkọ̀ náà má bàa fì síbí fì sọ́hùn-ún mọ́, wọ́n ṣe àwọn nǹkan sábẹ́ ọkọ̀ náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ méjèèjì. Àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe náà kì í jẹ́ kí ọkọ̀ náà fì ju bó ṣe yẹ lọ, ó sì máa ń jẹ́ kí ọkàn àwọn tó wà nínú ẹ̀ balẹ̀. Àmọ́ ìgbà tí àwọn nǹkan yẹn máa ń ṣiṣẹ́ jù ni ìgbà tí ọkọ̀ náà bá ń lọ síwájú. Lọ́nà kan náà, Jèhófà máa fi wá lọ́kàn balẹ̀ tá a bá ń tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀ láìka àwọn ìṣòro tá a ní sí. w24.01 22 ¶7-8
Wednesday, December 31
Ìwọ [Ọlọ́run] ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; ẹ̀rù ò bà mí.—Sm. 56:4.
Tẹ́rù bá ń bà ẹ́, bi ara ẹ pé, ‘Kí làwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe?’ Ronú nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá “fara balẹ̀ kíyè sí” bí Jèhófà ṣe ń tọ́jú àwọn ẹyẹ àti òdòdó bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò dá wọn ní àwòrán ẹ̀, tí wọn ò sì lè jọ́sìn ẹ̀, ó máa jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e pé á bójú tó àwa náà. (Mát. 6:25-32) Tún wo ohun tí Jèhófà ti ṣe fáwọn tó ń sìn ín. O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹnì kan nínú Bíbélì tí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lágbára gan-an tàbí kó o ka ìtàn ìgbésí ayé ìránṣẹ́ Jèhófà kan lóde òní. Yàtọ̀ síyẹn, ronú nípa bí Jèhófà ṣe bójú tó ẹ. Báwo ló ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o fi kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? (Jòh. 6:44) Báwo ló ṣe dáhùn àdúrà ẹ? (1 Jòh. 5:14) Àǹfààní wo ni ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ń ṣe ẹ́ lójoojúmọ́?—Éfé. 1:7; Héb. 4:14-16. w24.01 3 ¶6; 7 ¶17