November
Saturday, November 1
Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ jòjòló lo ti mú kí ìyìn jáde.—Mát. 21:16.
Tó o bá jẹ́ òbí, bá àwọn ọmọ ẹ múra ìdáhùn tó máa rọrùn fún wọn láti sọ. Nígbà míì, àpilẹ̀kọ kan lè dá lórí ìṣòro táwọn tọkọtaya máa ń ní tàbí kó dá lórí ìwà mímọ́, àmọ́ ìpínrọ̀ kan tàbí méjì máa wà níbẹ̀ táwọn ọmọdé ti lè dáhùn. Bákan náà, jẹ́ káwọn ọmọ ẹ mọ̀ pé gbogbo ìgbà tí wọ́n bá nawọ́ kọ́ ni wọ́n máa pè wọ́n. Tó o bá ti ṣàlàyé fún wọn ṣáájú, inú ò ní bí wọn tí wọn ò bá pè wọ́n àmọ́ tí wọ́n pe àwọn ẹlòmíì. (1 Tím. 6:18) Gbogbo wa la lè múra ìdáhùn tó máa bọlá fún Jèhófà, tó sì máa gbé àwọn ará ró. (Òwe 25:11) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè sọ ìrírí ara wa ní ṣókí, ó tún yẹ ká ṣọ́ra ká má máa sọ̀rọ̀ nípa ara wa jù. (Òwe 27:2; 2 Kọ́r. 10:18) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká fi ìdáhùn wa yin Jèhófà lógo, ká fi ṣàlàyé Bíbélì, ká sì tún fi sọ ìrírí àwọn ará wa.—Ìfi. 4:11. w23.04 24-25 ¶17-18
Sunday, November 2
Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn bí àwọn yòókù ti ń ṣe, àmọ́ ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò, kí a sì máa ronú bó ṣe tọ́.—1 Tẹs. 5:6.
Ìfẹ́ ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ wà lójúfò, ká sì ronú lọ́nà tó tọ́. (Mát. 22:37-39) Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń bá ìṣòro pàdé. (2 Tím. 1:7, 8) Torí pé a tún nífẹ̀ẹ́ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a máa ń wàásù fún wọn. Kódà, a máa ń wàásù fún wọn látorí fóònù àti nípasẹ̀ lẹ́tà. A ò jẹ́ kó sú wa torí a mọ̀ pé lọ́jọ́ kan, àwọn tá à ń wàásù fún máa yí pa dà, wọ́n sì máa ṣe ohun tó tọ́. (Ìsík. 18:27, 28) A tún nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa náà. A máa ń fi irú ìfẹ́ yẹn hàn tá a bá ń ‘fún ara wa níṣìírí, tá a sì ń gbé ara wa ró.’ (1 Tẹs. 5:11) A máa ń fún ara wa níṣìírí bíi tàwọn sójà tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn lójú ogun. A ò ní mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó máa dun àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a ò sì ní fi búburú san búburú fún wọn. (1 Tẹs. 5:13, 15) A tún ń fi ìfẹ́ yẹn hàn tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó wa nínú ìjọ.—1 Tẹs. 5:12. w23.06 10 ¶6; 11 ¶10-11
Monday, November 3
Tí [Jèhófà] bá sọ ohun kan, ṣé kò ní ṣe é?—Nọ́ń. 23:19.
Ọ̀nà kan tá a lè gbà mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára ni pé ká máa ronú lórí bí Ọlọ́run ṣe fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà. Ìràpadà jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Tá a bá ronú dáadáa lórí ìdí tí Ọlọ́run fi pèsè ìràpadà àtohun tó ṣe kí ìràpadà náà lè ṣeé ṣe, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára pé ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí máa dé níbi tá ò ti ní kú mọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Kí ni Jèhófà ṣe láti rà wá pa dà? Jèhófà rán àkọ́bí ẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ gan-an, tó sún mọ́ ọn jù lọ látọ̀run kí wọ́n lè bí i sáyé ní ẹni pípé. Nígbà tí Jésù wá sáyé, ó fara da onírúurú ìṣòro tó dé bá a. Lẹ́yìn náà, ìyà jẹ ẹ́, ó sì kú ikú oró. Ẹ ò rí i pé nǹkan kékeré kọ́ ni Jèhófà ṣe láti rà wá pa dà! Tó bá jẹ́ pé àkókò díẹ̀ la máa fi gbádùn ìràpadà náà, Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa ò ní gbà láé kí ìyà jẹ Ọmọ ẹ̀ kó sì kú. (Jòh. 3:16; 1 Pét. 1:18, 19) Torí náà, tí Jèhófà bá lè fi Ọmọ ẹ̀ kan ṣoṣo rà wá pa dà, ó dájú pé á jẹ́ kí ayé tuntun tó ṣèlérí dé, níbi tá ò ti ní kú mọ́. w23.04 27 ¶8-9
Tuesday, November 4
Ìwọ Ikú, oró rẹ dà?—Hós. 13:14.
Ṣé ó wu Jèhófà láti jí àwọn òkú dìde? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wù ú. Ó fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ darí àwọn kan tó kọ Bíbélì pé kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ìlérí tí òun ṣe pé òun máa jí àwọn òkú dìde lọ́jọ́ iwájú. (Àìsá. 26:19; Ìfi. 20:11-13) Gbogbo ìgbà tí Jèhófà bá sì ṣèlérí ló máa ń mú un ṣẹ. (Jóṣ. 23:14) Torí náà, ó wu Jèhófà láti jí àwọn òkú dìde. Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Jóòbù sọ yẹ̀ wò. Ó dá Jóòbù lójú pé tóun bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí òun dìde. (Jóòbù 14:14, 15, àlàyé ìsàlẹ̀) Bó ṣe ń wu Jèhófà náà nìyẹn láti jí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó ti kú dìde. Ó wù ú kó jí wọn dìde, kí wọ́n ní ìlera tó jí pépé, kí wọ́n sì máa láyọ̀. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àìmọye èèyàn tí wọn ò láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà kí wọ́n tó kú? Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa máa jí àwọn náà dìde. (Ìṣe 24:15) Ó fẹ́ káwọn náà di ọ̀rẹ́ òun, kí wọ́n sì máa gbé ayé títí láé.—Jòh. 3:16. w23.04 9 ¶5-6
Wednesday, November 5
Ọlọ́run ló máa fún wa lágbára.—Sm. 108:13.
Báwo lo ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú àwọn ìlérí Jèhófà túbọ̀ lágbára? Bí àpẹẹrẹ, tó o bá nírètí láti gbé ayé títí láé, ka ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Párádísè ṣe máa rí, kó o sì ronú lé e lórí. (Àìsá. 25:8; 32:16-18) Ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun. Máa fojú inú wo ara ẹ níbẹ̀. Tá a bá ń fojú inú wo àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ nínú ayé tuntun, àá rí i pé “ìgbà díẹ̀” ló kù káwọn ìṣòro wa dópin, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n bò wá mọ́lẹ̀. (2 Kọ́r. 4:17) Àwọn ohun tí Jèhófà ṣèlérí yìí máa fún ẹ lókun. Ó sì ti pèsè àwọn nǹkan táá máa fún ẹ lókun. Torí náà, tó o bá fẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ kan tí wọ́n gbé fún ẹ, kó o fara da ìṣòro ẹ, kó o sì máa láyọ̀ nìṣó, gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn, kó o sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́ kó o lè rí ìtọ́sọ́nà ẹ̀. Jẹ́ kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ràn ẹ́ lọ́wọ́. Máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run máa lo ‘agbára rẹ̀ ológo láti fún ẹ ní gbogbo agbára tó o nílò, kó o lè fara dà á pẹ̀lú sùúrù àti ìdùnnú.’—Kól. 1:11. w23.10 17 ¶19-20
Thursday, November 6
Ẹ máa dúpẹ́ ohun gbogbo.—1 Tẹs. 5:18.
Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe fún wa tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ tá a bá ń gbàdúrà. Ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ torí àwọn ohun rere tó ṣe fún wa, ó ṣe tán, ọ̀dọ̀ ẹ̀ ni gbogbo ẹ̀bùn rere ti wá. (Jém. 1:17) Bí àpẹẹrẹ, a lè dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pé ó dá ayé tó rẹwà yìí àtàwọn nǹkan àgbàyanu míì. A tún lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń bójú tó wa, ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa àti pé ó jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ó tún yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́. Téèyàn bá mọnú rò, á mọpẹ́ dá. Torí náà, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣe fún wa. Nínú ayé tá à ń gbé lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò moore. Ohun táwọn èèyàn gbájú mọ́ ni bí wọ́n ṣe máa rí ohun tí wọ́n fẹ́, dípò kí wọ́n máa dúpẹ́ nítorí ohun tí wọ́n ní. Táwa náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í hu irú ìwà yìí, ó lè mú ká máa béèrè ohun tá a fẹ́ nìkan lọ́wọ́ Jèhófà. Tá ò bá fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí gbogbo ohun tó ń ṣe fún wa.—Lúùkù 6:45. w23.05 4 ¶8-9
Friday, November 7
Máa fi ìgbàgbọ́ béèrè, má ṣiyèméjì rárá.—Jém. 1:6.
Torí pé Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ wa ni Jèhófà, kì í fẹ́ ká máa jẹ̀rora. (Àìsá. 63:9) Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ìṣòro wa tó dà bí odò tàbí iná ló máa ń mú kúrò. (Àìsá. 43:2) Ṣùgbọ́n, ó ti ṣèlérí pé òun máa wà ‘pẹ̀lú wa,’ kò sì ní jẹ́ kí ìṣòro mú ká fi òun sílẹ̀. Jèhófà tún máa ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ká lè fara dà á. (Lúùkù 11:13; Fílí. 4:13) Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà á máa pèsè ohun tá a nílò, ká lè máa fara da ìṣòro wa ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí i. Jèhófà fẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé òun. (Héb. 11:6) Nígbà míì, ìṣòro wa lè dà bí òkè ńlá. Kódà, ó lè ṣe wá bíi pé Jèhófà ò ní ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́ Bíbélì fi dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa lágbára tá a lè fi “gun ògiri.” (Sm. 18:29) Torí náà, dípò ká máa ṣiyèméjì, ṣe ló yẹ ká máa gbàdúrà, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá pé ó máa dáhùn àdúrà wa.—Jém. 1:6, 7. w23.11 22 ¶8-9
Saturday, November 8
Ọwọ́ iná [ìfẹ́] dà bí iná tó ń jó, ọwọ́ iná Jáà. Omi tó ń ru gùdù ò lè paná ìfẹ́, odò kò sì lè gbé e lọ.—Orin Sól. 8:6, 7.
Ẹ ò rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ tó dùn ni Bíbélì fi ṣàpèjúwe ìfẹ́ tòótọ́! Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí fi àwọn tọkọtaya lọ́kàn balẹ̀ pé wọ́n lè ní ìfẹ́ tòótọ́ síra wọn. Táwọn tọkọtaya bá máa ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ síra wọn títí láé, ọwọ́ wọn ló wà. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá dáná igi, tá a sì ń koná mọ́ ọn, kò ní kú. Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí i tá ò bá koná mọ́ ọn? Ó dájú pé ó máa kú. Lọ́nà kan náà, ìfẹ́ tó wà láàárín ọkọ àti aya kan á máa lágbára sí i tí wọ́n bá ń koná mọ́ ọn. Àmọ́ nígbà míì, ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn tọkọtaya kan lè má lágbára mọ́ torí ìṣòro ìṣúnná owó, àìsàn tàbí torí pé kò rọrùn fún wọn láti tọ́ àwọn ọmọ wọn. Kí “ọwọ́ iná Jáà” tó lè máa jó láàárín yín, ẹ̀yin tọkọtaya gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí àjọṣe yín pẹ̀lú Jèhófà lè lágbára. w23.05 20-21 ¶1-3
Sunday, November 9
Má bẹ̀rù.—Dán. 10:19.
Kí ló yẹ ká ṣe ká lè nígboyà? Àwọn òbí wa lè rọ̀ wá pé ká nígboyà, àmọ́ a ò lè jogún ìgboyà látọ̀dọ̀ wọn. Tẹ́nì kan bá fẹ́ nígboyà, ṣe ló máa kọ́ bó ṣe máa ní in. Bó o ṣe lè nígboyà ni pé kó o máa wo ohun tẹ́ni tó nígboyà ń ṣe, kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá fẹ́ kọ́ ìgboyà, ó yẹ ká máa wo báwọn èèyàn ṣe ń fi ànímọ́ yìí hàn, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Bíi ti Dáníẹ́lì, ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Ó yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, ká máa sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa fún un kí àjọṣe wa lè túbọ̀ lágbára. Ó tún yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé e, kó sì dá wa lójú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́. Tí nǹkan kan bá wá dán wa wò, àá lè fìgboyà kojú ẹ̀. Àwọn èèyàn máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn tó nígboyà. Wọ́n tún lè mú káwọn èèyàn wá mọ Jèhófà. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká nígboyà! w23.08 2 ¶2; 4 ¶8-9
Monday, November 10
Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú.—1 Tẹs. 5:21.
Àwọn èèyàn máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà ‘wádìí dájú’ tí wọ́n bá fẹ́ mọ̀ bóyá ojúlówó ni òkúta iyebíye kan bíi wúrà tàbí fàdákà. Torí náà, ó yẹ káwa náà dán ohun tá a gbọ́ tàbí ohun tá a kà wò bóyá wọ́n jẹ́ òótọ́, ó sì ṣe pàtàkì pé káwa náà ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí pàápàá bí ìpọ́njú ńlá ṣe ń sún mọ́lé. Dípò ká kàn máa gba gbogbo nǹkan táwọn èèyàn bá sọ gbọ́, ó yẹ ká máa lo làákàyè wa láti fi ohun tá a gbọ́ àtohun tá a kà wé ohun tí Bíbélì àti ètò Ọlọ́run sọ. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọn ò ní fi ìkéde irọ́ táwọn ẹ̀mí èṣù mí sí tàn wá jẹ. (Òwe 14:15; 1 Tím. 4:1) Àwa èèyàn Jèhófà lápapọ̀ máa la ìpọ́njú ńlá já. Àmọ́ a ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́la. (Jém. 4:14) Bóyá a máa la ìpọ́njú ńlá já tàbí a máa kú kó tó bẹ̀rẹ̀, ohun tó dájú ni pé tá a bá jẹ́ olóòótọ́, a máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa gbájú mọ́ èrè tí Ọlọ́run fẹ́ fún wa, ká sì máa múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà! w23.06 13 ¶15-16
Tuesday, November 11
Ó ti fi àṣírí ọ̀rọ̀ náà han àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Émọ́sì 3:7.
A ò mọ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ṣe máa ṣẹ. (Dán. 12:8, 9) Àmọ́, tá ò bá tiẹ̀ mọ bí àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣe máa ṣẹ, ìyẹn ò sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ náà ò ní ṣẹ. Ó dá wa lójú pé ní àkókò tó yẹ, Jèhófà máa jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, bó ti ṣe nígbà àtijọ́. Àwọn orílẹ̀-èdè máa kéde “àlàáfíà àti ààbò.” (1 Tẹs. 5:3) Lẹ́yìn náà, àwọn ìjọba ayé máa gbéjà ko ìsìn èké, wọ́n sì máa pa á run. (Ìfi. 17:16, 17) Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n máa gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run. (Ìsík. 38:18, 19) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 16:14, 16) Ó dá wa lójú pé àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. Kó tó dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká máa kíyè sí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ká sì máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ káwọn náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹn ló máa fi hàn pé a mọyì gbogbo ohun tí Jèhófà Bàbá wa ọ̀run ń ṣe fún wa. w23.08 13 ¶19-20
Wednesday, November 12
Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa, torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá.—1 Jòh. 4:7.
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́, ohun tó fi parí ọ̀rọ̀ ẹ̀ ni pé “èyí tó tóbi jù lọ nínú [àwọn ànímọ́ yìí] ni ìfẹ́.” (1 Kọ́r. 13:13) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé lọ́jọ́ iwájú, kò ní sídìí fún wa mọ́ láti nígbàgbọ́ nínú àwọn nǹkan tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe nínú ayé tuntun tàbí ká máa retí pé ó máa mú àwọn ìlérí náà ṣẹ torí pé gbogbo ẹ̀ ló ti máa ṣẹ. Àmọ́ ìgbà gbogbo làá máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn. Kódà, títí ayé làá máa nífẹ̀ẹ́ wọn. Bákan náà, ìfẹ́ wà lára ohun tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé: “Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.” (Jòh. 13:35) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, a máa wà níṣọ̀kan. Pọ́ọ̀lù sọ pé ìfẹ́ ni “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kól. 3:14) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ fáwọn Kristẹni pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.” (1 Jòh. 4:21) Torí náà, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, ìyẹn máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. w23.11 8 ¶1, 3
Thursday, November 13
Ju gbogbo ẹrù tó wúwo nù.—Héb. 12:1.
Bíbélì fi ìgbésí ayé àwa Kristẹni wé eré sísá. Àwọn tó bá sá eré náà parí máa gba èrè ìyè àìnípẹ̀kun. (2 Tím. 4:7, 8) Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè sá eré náà parí torí a ti sún mọ́ òpin eré náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe káwa náà lè sá eré náà parí ká sì gba èrè. Ó sọ pé ká “ju gbogbo ẹrù tó wúwo nù . . . ká sì máa fi ìfaradà sá eré ìje tó wà níwájú wa.” Ṣé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé àwa Kristẹni ò ní gbé ẹrù kankan? Rárá, ohun tó ń sọ kọ́ nìyẹn. Ohun tó ń sọ ni pé ká ju àwọn ẹrù tí ò yẹ nù. Àwọn ẹrù tí ò yẹ yẹn lè dí wa lọ́wọ́, wọn ò sì ní jẹ́ ká sáré náà parí. Ká bàa lè sá eré náà parí, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn ẹrù náà, ká lè sọ wọ́n nù. Bákan náà, àwọn ẹrù kan wà tó yẹ ká gbé dání, kò sì yẹ ká jù wọ́n nù. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a ò ní lè sá eré náà parí.—2 Tím. 2:5. w23.08 26 ¶1-2
Friday, November 14
Kí ẹwà yín má ṣe jẹ́ ti òde ara.—1 Pét. 3:3.
Tá a bá ń fòye báni lò, a ò ní máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arábìnrin wa kan fẹ́ràn kí wọ́n máa tọ́jú tọ́tè, àwọn arábìnrin kan ò sì fẹ́ràn kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ará wa kan máa ń mutí níwọ̀nba, àwọn kan kì í sì í mu ún rárá. Gbogbo àwa Kristẹni ló máa ń wù pé ká ní ìlera tó jí pépé, àmọ́ ìtọ́jú tá a máa ń gbà yàtọ̀ síra. Tá a bá ń fipá mú àwọn ará nínú ìjọ pé kí wọ́n ṣe ohun tá a fẹ́, a lè mú àwọn ará kọsẹ̀, ó sì lè dá ìyapa sílẹ̀ láàárín wa. (1 Kọ́r. 8:9; 10:23, 24) Bí àpẹẹrẹ, kàkà kí Jèhófà ṣòfin nípa irú aṣọ tá a máa wọ̀, ṣe ló fún wa láwọn ìlànà tí àá máa tẹ̀ lé. Ó yẹ ká máa múra lọ́nà tó yẹ àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run, kó fi hàn pé à ń fòye báni lò, a mọ̀wọ̀n ara wa, a sì ní “àròjinlẹ̀.” (1 Tím. 2:9, 10) Torí náà, tí ìmúra wa ò bá bójú mu, ó lè jẹ́ káwọn èèyàn máa wò wá láwòyanu. Bákan náà, táwọn alàgbà bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, wọn ò ní máa gbé ìlànà tara wọn kalẹ̀ nípa irú aṣọ táwọn ará máa wọ̀ àti irú irun tó yẹ kí wọ́n ṣe. w23.07 23-24 ¶13-14
Saturday, November 15
Ẹ tẹ́tí sí mi dáadáa, kí ẹ sì jẹ ohun tó dáa, ohun tó dọ́ṣọ̀ sì máa mú inú yín dùn gidigidi.—Àìsá. 55:2.
Jèhófà ní kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ohun tó máa jẹ́ ká láyọ̀. Ìṣekúṣe táwọn tó lọ sọ́dọ̀ “òmùgọ̀ obìnrin” tó ń kígbe pè wọ́n fẹ́ ‘gbádùn’ ló jẹ́ kí wọ́n lọ síbẹ̀. Ibi tí wọ́n ti máa bá ara wọn ni “ìsàlẹ̀ Isà Òkú.” (Òwe 9:13, 17, 18) Àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tó lọ sọ́dọ̀ obìnrin tó ṣàpẹẹrẹ “ọgbọ́n tòótọ́” yàtọ̀ pátápátá! (Òwe 9:1) Torí náà, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ohun tí Jèhófà fẹ́, ká sì kórìíra àwọn ohun tí ò fẹ́. (Sm. 97:10) Yàtọ̀ síyẹn, inú wa máa ń dùn láti pe àwọn èèyàn pé káwọn náà wá jàǹfààní lára “ọgbọ́n tòótọ́.” Ṣe ló dà bí ìgbà tá à ń “ké jáde látorí àwọn ibi gíga ìlú pé: ‘Kí ẹni tó bá jẹ́ aláìmọ̀kan wọlé síbí.’” Àwa àtàwọn tó ń fetí sí wa máa jàǹfààní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn lá jẹ́ ká “wà láàyè” títí láé bá a ṣe ń “rìn ní ọ̀nà òye nìṣó.”—Òwe 9:3, 4, 6. w23.06 24 ¶17-18
Sunday, November 16
Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju akíkanjú ọkùnrin, ẹni tó sì ń kápá ìbínú rẹ̀ sàn ju ẹni tó ṣẹ́gun ìlú.—Òwe 16:32.
Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tẹ́ni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí ọmọ ilé ìwé ẹ bá bi ẹ́ nípa ohun tó o gbà gbọ́? Ṣé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́? Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ lára wa lẹ̀rù máa ń bà. Àmọ́, irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ká mọ ohun tẹ́ni náà ń rò àtohun tó gbà gbọ́. Ìyẹn sì lè ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti wàásù fún un. Nígbà míì, àwọn kan máa ń béèrè ìbéèrè torí pé wọn ò fara mọ́ ohun tá a gbà gbọ́ tàbí torí kí wọ́n lè bá wa jiyàn. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu. Ìdí ni pé wọ́n ti sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn kan. (Ìṣe 28:22) Ìdí míì ni pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ “kìígbọ́-kìígbà,” tí wọ́n sì “burú gan-an” là ń gbé báyìí. (2 Tím. 3:1, 3) O lè máa ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́, kí n sì sọ̀rọ̀ tó tura tẹ́nì kan bá fẹ́ bá mi jiyàn nípa ohun tí mo gbà gbọ́?’ Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ìwà tútù ni. Ẹni tó bá níwà tútù kì í tètè bínú, ó máa ń kó ara ẹ̀ níjàánu tí wọ́n bá múnú bí i tàbí tí kò bá mọ ohun tó máa sọ. w23.09 14 ¶1-2
Monday, November 17
Wàá yàn wọ́n ṣe olórí ní gbogbo ayé.—Sm. 45:16.
Nígbà míì, ètò Ọlọ́run máa ń tọ́ wa sọ́nà, wọ́n sì máa ń dáàbò bò wá ká má bàa nífẹ̀ẹ́ owó tàbí ká ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ ká rú òfin Ọlọ́run. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa láwọn apá yìí, Jèhófà máa bù kún wa. (Àìsá. 48:17, 18; 1 Tím. 6:9, 10) Kò sí àní-àní pé Jèhófà á ṣì máa lo àwọn èèyàn láti tọ́ wa sọ́nà nígbà ìpọ́njú ńlá títí dìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Ṣé àá ṣì máa ṣe ohun tí wọ́n bá sọ fún wa? Ó máa rọrùn fún wa nígbà yẹn tá a bá ń ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ fún wa báyìí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jèhófà nígbà gbogbo títí kan èyí tí àwọn tí Jèhófà ní kó máa bójú tó wa bá fún wa. (Àìsá. 32:1, 2; Héb. 13:17) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa fọkàn tán Jèhófà Ẹni tó ń tọ́ wa sọ́nà, tó ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ jẹ́, tó sì máa jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun. w24.02 25 ¶17-18
Tuesday, November 18
Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ mú kí ẹ rí ìgbàlà.—Éfé. 2:5.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbádùn iṣẹ́ tó ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àmọ́ ó ní àwọn ìṣòro kan. Ó máa ń rìnrìn àjò lọ sáwọn ibi tó jìnnà gan-an, bẹ́ẹ̀ sì rèé ìrìn àjò ò rọrùn nígbà yẹn. Nígbà míì, tó bá ń rìnrìn àjò, ọkàn ẹ̀ kì í balẹ̀ nítorí ‘ewu odò àtàwọn dánàdánà.’ Àwọn ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé àwọn alátakò máa ń fìyà jẹ ẹ́. (2 Kọ́r. 11:23-27) Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe gbogbo ìgbà làwọn ará máa ń mọyì ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (2 Kọ́r. 10:10; Fílí. 4:15) Kí ló jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù máa bá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà nìṣó? Ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni pé ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà látinú Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìrírí tóun fúnra ẹ̀ ní. Torí náà, ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. (Róòmù 8:38, 39; Éfé. 2:4, 5) Ìyẹn mú kóun náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà torí ó ń “ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́,” ó “sì ń bá a lọ láti ṣe ìránṣẹ́.”—Héb. 6:10. w23.07 9 ¶5-6
Wednesday, November 19
Máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga.—Róòmù 13:1.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé a nílò ìjọba táá máa ṣàkóso wa àti pé ó yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn òfin kan tí “àwọn aláṣẹ onípò gíga” yìí bá ṣe. Àmọ́ táwọn èèyàn yìí bá rí i pé àwọn òfin kan ò tẹ́ àwọn lọ́rùn tàbí tí wọ́n rí i pé ó nira, wọn kì í pa á mọ́. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìjọba èèyàn máa ń ṣe ohun tó ń pa àwọn aráàlú lára, ó sì sọ pé Sátánì ló ń darí àwọn ìjọba yẹn àti pé wọ́n máa pa run láìpẹ́. (Sm. 110:5, 6; Oníw. 8:9; Lúùkù 4:5, 6) Ó tún sọ fún wa pé “ẹni tó bá ta ko aláṣẹ ta ko ètò tí Ọlọ́run ṣe.” Ní báyìí, Jèhófà ṣì fàyè gba ìjọba èèyàn láti máa ṣàkóso kí nǹkan lè wà létòlétò, ó sì retí pé ká máa ṣègbọràn sí wọn. Torí náà, a gbọ́dọ̀ “fún gbogbo èèyàn ní ohun tí ó tọ́ sí wọn,” ìyẹn ni pé ká máa san owó orí, ká máa bọ̀wọ̀ fún wọn, ká sì máa pa òfin mọ́. (Róòmù 13:1-7) Lóòótọ́, òfin kan lè nira, ó lè má tẹ́ wa lọ́rùn tàbí kó ṣòro fún wa láti pa mọ́. Àmọ́, a máa ń ṣègbọràn torí Jèhófà ló sọ pé ká ṣe bẹ́ẹ̀, tí òfin tí wọ́n ṣe ò bá ṣáà ti ta ko òfin Jèhófà.—Ìṣe 5:29. w23.10 8 ¶9-10
Thursday, November 20
Ẹ̀mí Jèhófà fún un lágbára.—Oníd. 15:14.
Nígbà tí wọ́n bí Sámúsìn, àwọn Filísínì ló ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń jẹ gàba lé wọn lórí. (Oníd. 13:1) Àwọn Filísínì rorò gan-an, wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Torí náà, Jèhófà yan Sámúsìn pé kó “ṣáájú láti gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Filísínì.” (Oníd. 13:5) Kí Sámúsìn tó lè ṣe iṣẹ́ tó le yìí, ó gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ìgbà kan wà táwọn ọmọ ogun Filísínì wá mú Sámúsìn ní Léhì, tó ṣeé ṣe kó wà ní Júdà. Torí pé ẹ̀rù ń ba àwọn ọkùnrin Júdà, wọ́n pinnu pé àwọn á jẹ́ káwọn ọ̀tá mú Sámúsìn lọ. Torí náà, àwọn èèyàn Júdà fi okùn tuntun méjì de Sámúsìn, wọ́n sì mú un wá fún àwọn Filísínì. (Oníd. 15:9-13) Àmọ́, “ẹ̀mí Jèhófà fún un lágbára,” ó sì já àwọn okùn náà dà nù. Lẹ́yìn náà, ó rí “egungun tútù kan tó jẹ́ egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,” ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ọkùnrin!—Oníd. 15:14-16. w23.09 2 ¶3-4
Friday, November 21
Èyí bá ìpinnu rẹ̀ ayérayé mu, tí ó ṣe ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, Jésù Olúwa wa.—Éfé. 3:11.
Díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà ń jẹ́ ká mọ “ìpinnu rẹ̀ ayérayé” nínú Bíbélì. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Jèhófà lè gbà ṣe ohun tó fẹ́ ṣe, ó sì máa ń yọrí sí rere torí pé ó “ti mú kí gbogbo nǹkan rí bó ṣe fẹ́.” (Òwe 16:4) Ohunkóhun tí Jèhófà bá sì ṣe máa wà títí láé. Torí náà, a lè bi ara wa pé kí ni Jèhófà fẹ́ ṣe, àwọn àyípadà wo ló sì ti ṣe kó lè ṣe ohun tó fẹ́? Jèhófà sọ ohun tó fẹ́ kí Ádámù àti Éfà ṣe fún wọn. Ó sọ pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ máa jọba lórí . . . gbogbo ohun alààyè” tó wà láyé. (Jẹ́n. 1:28) Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, tí wọ́n sì mú kí gbogbo èèyàn di ẹlẹ́ṣẹ̀, ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún aráyé ò yí pa dà. Ṣe ló kàn yí ọ̀nà tó fẹ́ gbà ṣe é pa dà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló pinnu láti gbé Ìjọba kan kalẹ̀ lọ́run tó máa mú kí ohun tó fẹ́ ṣe fáwa èèyàn àti ayé yìí ṣẹ.—Mát. 25:34. w23.10 19-20 ¶6-7
Saturday, November 22
Tí kì í bá ṣe ti Jèhófà tó ràn mí lọ́wọ́, ká tó ṣẹ́jú pẹ́ ni ǹ bá ti ṣègbé.—Sm. 94:17.
Jèhófà máa ran àwa náà lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín nìṣó. Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, pàápàá tó bá ti pẹ́ tá a ti ní kùdìẹ̀-kudiẹ kan tá à ń bá yí. Nígbà míì, kùdìẹ̀-kudiẹ wa lè burú ju ti àpọ́sítélì Pétérù lọ. Àmọ́, Jèhófà máa fún wa lókun ká lè máa sìn ín nìṣó. (Sm. 94:18, 19) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni arákùnrin kan ti ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ kó tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ohun tó kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ kó fi ìwà náà sílẹ̀ pátápátá. Síbẹ̀, nígbà míì, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí máa ń wá sí i lọ́kàn. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: ‘Jèhófà ló ń fún mi lókun. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, ó sì ti jẹ́ kí n rí i pé mo lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Bí mo tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, Jèhófà ń lò mí, ó sì ń fún mi lókun.’ w23.09 23 ¶12
Sunday, November 23
Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.—Òwe 22:4.
Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, òtítọ́ ò lè ṣàdédé jinlẹ̀ nínú yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kẹ́ ẹ fara wé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, kẹ́ ẹ ní àròjinlẹ̀, kẹ́ ẹ ṣeé fọkàn tán, kẹ́ ẹ kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe yín láǹfààní, kẹ́ ẹ sì múra sílẹ̀ de àwọn ojúṣe tẹ́ ẹ máa ní lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá ronú nípa gbogbo nǹkan tó yẹ kó o ṣe yìí, ó lè kà ẹ́ láyà. Àmọ́, o lè ṣàṣeyọrí. Máa rántí pé ó wu Jèhófà láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Àìsá. 41:10, 13) Ó sì dájú pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nínú ìjọ tún máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá di Kristẹni ọkùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ayé ẹ máa dáa, wàá sì láyọ̀. Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin wa, a nífẹ̀ẹ́ yín gan-an! Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà bù kún yín bẹ́ ẹ ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. w23.12 29 ¶19-20
Monday, November 24
Gbójú fo àṣìṣe.—Òwe 19:11.
Ká sọ pé ìwọ àtàwọn ará wà níbi ìkórajọ kan tẹ́ ẹ̀ ń gbádùn ara yín, o sì ya fọ́tò gbogbo yín. Kódà, o ya fọ́tò méjì míì torí ó ṣeé ṣe kí tàkọ́kọ́ má dáa. Ní báyìí, o ti ní fọ́tò mẹ́ta. Àmọ́, o kíyè sí pé arákùnrin kan lejú koko nínú ọ̀kan lára àwọn fọ́tò yẹn. Torí náà, ńṣe lo yọ ọ́ kúrò torí o ṣì ní fọ́tò méjì míì tí gbogbo yín ti rẹ́rìn ín, títí kan arákùnrin yẹn. A máa ń rántí àwọn nǹkan dáadáa táwa àtàwọn ará jọ ṣe. Àmọ́, ká sọ pé nígbà kan, ọ̀kan lára wọn sọ tàbí ṣe ohun tí ò dáa sí ẹ. Ṣé ó yẹ kó o gbé e sọ́kàn? O ò ṣe gbé e kúrò lọ́kàn, bí ìgbà tó o yọ fọ́tò tí ò dáa yẹn kúrò? (Éfé. 4:32) Ó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan rere làwa àtẹni náà ti jọ ṣe tá a lè fi máa rántí ẹ̀. Irú àwọn nǹkan dáadáa táwọn ará ti ṣe yìí ló yẹ ká máa rántí, ká sì mọyì ẹ̀. w23.11 12 ¶16-17
Tuesday, November 25
Kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tó bójú mu ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, . . . lọ́nà tó yẹ àwọn obìnrin tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn.—1 Tím. 2:9, 10.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí i pé obìnrin Kristẹni kan gbọ́dọ̀ máa wọ aṣọ tó buyì kúnni, kí aṣọ náà sì fi hàn pé ó gba tàwọn ẹlòmíì rò. A mọyì ẹ̀yin arábìnrin wa gan-an torí pé ẹ máa ń múra dáadáa! Ànímọ́ míì tó yẹ kí gbogbo àwọn obìnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ní ni ìfòyemọ̀. Kí ni ìfòyemọ̀? Ìfòyemọ̀ ni kéèyàn mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, kó sì ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Ábígẹ́lì yẹ̀ wò. Ọkọ ẹ̀ ṣe ìpinnu kan tí ò dáa, ìyẹn sì máa kó gbogbo ìdílé wọn síṣòro. Ábígẹ́lì ò fọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rárá, ojú ẹsẹ̀ ló gbé ìgbésẹ̀. Torí pé ó jẹ́ olóye, ó gba agbo ilé ẹ̀ là. (1 Sám. 25:14-23, 32-35) Ìfòyemọ̀ tún máa ń jẹ́ ká mọ ìgbà tó yẹ ká sọ̀rọ̀ àtìgbà tó yẹ ká dákẹ́. Bákan náà, tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, ìfòyemọ̀ máa jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ láì tojú bọ ọ̀rọ̀ wọn.—1 Tẹs. 4:11. w23.12 20 ¶8-9
Wednesday, November 26
Ẹ jẹ́ kí a máa yọ̀, lórí ìrètí ògo Ọlọ́run.—Róòmù 5:2.
Ìjọ tó wà ní Róòmù ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yẹn sí. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà níbẹ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Jésù, wọ́n ti nígbàgbọ́, wọ́n sì ti di Kristẹni. Torí náà, Ọlọ́run “pè [wọ́n] ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́” tí wọ́n ní, ó sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. (Róòmù 5:1) Ìyẹn jẹ́ kó dá wọn lójú pé wọ́n máa rí ohun tí wọ́n ń retí gbà. Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní Éfésù nípa ìrètí tí wọ́n ní. Ọ̀kan lára ìrètí náà ni “ọrọ̀ ológo tó fẹ́ fi ṣe ogún fún àwọn ẹni mímọ́.” (Éfé. 1:18) Pọ́ọ̀lù tún jẹ́ káwọn ará tó wà ní Kólósè mọ ibi tí wọ́n á ti gba èrè wọn. Ó pè é ní “ìrètí tí a fi pa mọ́ dè yín ní ọ̀run.” (Kól. 1:4, 5) Ìrètí táwọn ẹni àmì òróró ní ni pé Ọlọ́run máa jí wọn dìde sí ọ̀run níbi tí wọ́n ti máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi, wọ́n sì máa wà láàyè títí láé.—1 Tẹs. 4:13-17; Ìfi. 20:6. w23.12 9 ¶4-5
Thursday, November 27
Àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín.—Fílí. 4:7.
Àwọn ológun ló máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ṣọ́,” ó sì ń tọ́ka sí àwọn sójà tó máa ń dáàbò bo ìlú kan káwọn ọ̀tá má bàa gbógun wọlé. Ọkàn àwọn ará ìlú táwọn sójà ń ṣọ́ máa ń balẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé àwọn tó ń ṣọ́ ìlú wà ní ẹnubodè. Lọ́nà kan náà, tí àlàáfíà Ọlọ́run bá ń ṣọ́ ọkàn àti ìrònú wa, ọkàn wa máa balẹ̀ torí a mọ̀ pé kò séwu fún wa. (Sm. 4:8) Bíi ti Hánà, tí ìṣòro wa ò bá tiẹ̀ yanjú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọkàn wa ṣì lè balẹ̀. (1 Sám. 1:16-18) Tí ọkàn wa bá sì balẹ̀, a máa ronú bó ṣe tọ́, àá sì ṣèpinnu tó dáa. Kí ló yẹ ká ṣe? Tá a bá níṣòro, ó yẹ ká ké pe Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Báwo la ṣe lè ṣe é? Gbàdúrà títí tó o fi máa rí àlàáfíà Ọlọ́run. (Lúùkù 11:9; 1 Tẹs. 5:17) Tó o bá níṣòro, máa gbàdúrà nígbà gbogbo, wàá rí i pé Jèhófà máa jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀.—Róòmù 12:12. w24.01 21 ¶5-6
Friday, November 28
Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́.—Mát. 6:9.
Kí Jésù lè sọ orúkọ Bàbá ẹ̀ di mímọ́, ó fara da ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́, ọ̀rọ̀ èébú tí wọ́n sọ sí i àti bí wọ́n ṣe bà á lórúkọ jẹ́. Ó mọ̀ pé òun ti ṣe gbogbo ohun tí Bàbá òun sọ pé kóun ṣe, ìdí nìyẹn tí ojú ò fi tì í torí ohun tí wọ́n ṣe fún un. (Héb. 12:2) Ó tún mọ̀ pé Sátánì ló ń fa gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àsìkò tí nǹkan nira fóun yẹn. (Lúùkù 22:2-4; 23:33, 34) Ohun tí Sátánì fẹ́ ni pé kí Jésù má jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà mọ́, àmọ́ kò rí i ṣe! Jésù fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé òpùrọ́ ni Sátánì àti pé a lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tá a bá tiẹ̀ ń kojú àdánwò tó le gan an! Ṣé ó wù ẹ́ pé kó o múnú Jésù Ọba wa dùn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, máa yin orúkọ Jèhófà, kó o sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tó jẹ́ àtàwọn ànímọ́ tó ní. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Jésù lò ń tẹ̀ lé yẹn. (1 Pét. 2:21) Bíi ti Jésù, wàá máa múnú Jèhófà dùn, wàá sì fi hàn pé òpùrọ́ gbáà ni Sátánì tó ń ta ko Jèhófà! w24.02 11 ¶11-13
Saturday, November 29
Kí ni màá san pa dà fún Jèhófà lórí gbogbo oore tó ṣe fún mi?—Sm. 116:12.
Lọ́dún márùn-ún sẹ́yìn, ó ju mílíọ̀nù kan àwọn èèyàn tó ṣèrìbọmi, tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, o di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi, o sì pinnu pé wàá máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà ní gbogbo ìgbà. Kí làwọn nǹkan tó máa ná ẹ tó o bá ya ara ẹ sí mímọ́? Jésù sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀.” (Mát. 16:24) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “kó sẹ́ ara rẹ̀” tún lè túmọ̀ sí “kéèyàn kọ̀ láti ṣe nǹkan kan.” Tó o bá ti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, o gbọ́dọ̀ pinnu pé o ò ní ṣe ohunkóhun tínú Jèhófà ò dùn sí. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Lára àwọn nǹkan náà ni “àwọn iṣẹ́ ti ara,” irú bí ìṣekúṣe. (Gál. 5:19-21; 1 Kọ́r. 6:18) Ṣé àwọn nǹkan yìí máa nira fún ẹ láti ṣe? Tó o bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó o sì gbà pé ohun tó dáa ló fẹ́ fún ẹ, kò ní nira fún ẹ láti pa àwọn òfin ẹ̀ mọ́.—Sm. 119:97; Àìsá. 48:17, 18. w24.03 2 ¶1; 3 ¶4
Sunday, November 30
Mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.—Lúùkù 3:22.
Jèhófà máa ń fún àwọn tí inú ẹ̀ dùn sí ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀. (Mát. 12:18) O lè bi ara ẹ pé, ‘Ṣé ó hàn nínú ìwà mi pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí mi?’ Ṣé mo kíyè sí i pé mo ti túbọ̀ ń ní sùúrù fáwọn èèyàn báyìí ju ìgbà tí mo kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Bó o bá ṣe ń gbìyànjú tó láti jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí rẹ, tó o sì ní àwọn ìwà tí Bíbélì pè ní èso tẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ dá ẹ lójú pé inú Ọlọ́run ń dùn sí ẹ! Jèhófà máa ń jẹ́ kí àwọn tí inú ẹ̀ dùn sí jàǹfààní ìràpadà. (1 Tím. 2:5, 6) Àmọ́ tó bá ń ṣe wá bíi pé inú Jèhófà ò dùn sí wa ńkọ́? Bẹ́ẹ̀ sì rèé, a nígbàgbọ́ nínú ìràpadà, a sì ti ṣèrìbọmi. Ohun tó yẹ ká fi sọ́kàn ni pé ọkàn wa lè tàn wá jẹ, ó sì lè mú ká ronú lọ́nà tí kò tọ́. Àmọ́ ní ti Jèhófà, a lè fọkàn tán an. Ǹjẹ́ o mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo gbogbo àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ìràpadà? Ó gbà pé olódodo ni wọ́n, ó sì ṣèlérí pé òun máa bù kún wọn.—Sm. 5:12; Róòmù 3:26. w24.03 30 ¶15; 31 ¶17