ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es25 ojú ìwé 98-108
  • October

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • October
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Wednesday, October 1
  • Thursday, October 2
  • Friday, October 3
  • Saturday, October 4
  • Sunday, October 5
  • Monday, October 6
  • Tuesday, October 7
  • Wednesday, October 8
  • Thursday, October 9
  • Friday, October 10
  • Saturday, October 11
  • Sunday, October 12
  • Monday, October 13
  • Tuesday, October 14
  • Wednesday, October 15
  • Thursday, October 16
  • Friday, October 17
  • Saturday, October 18
  • Sunday, October 19
  • Monday, October 20
  • Tuesday, October 21
  • Wednesday, October 22
  • Thursday, October 23
  • Friday, October 24
  • Saturday, October 25
  • Sunday, October 26
  • Monday, October 27
  • Tuesday, October 28
  • Wednesday, October 29
  • Thursday, October 30
  • Friday, October 31
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
es25 ojú ìwé 98-108

October

Wednesday, October 1

Ọgbọ́n tó wá láti òkè . . . ṣe tán láti ṣègbọràn.—Jém. 3:17.

Nígbà míì, ṣé ó máa ń nira fún ẹ láti ṣègbọràn? Ó nira fún Ọba Dáfídì náà láti ṣègbọràn láwọn ìgbà kan, ìdí nìyẹn tó fi gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Jẹ́ kó máa wù mí láti ṣègbọràn sí ọ.” (Sm. 51:12) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó máa ń nira fún un láti ṣègbọràn, bọ́rọ̀ tiwa náà sì ṣe rí nìyẹn. Kí nìdí? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé àìpé tá a jogún ń mú ká ṣàìgbọràn. Ìkejì, Sátánì máa ń fẹ́ ká ṣọ̀tẹ̀ bíi tiẹ̀. (2 Kọ́r. 11:3) Ìkẹta, ìwà tinú mi ni màá ṣe ló pọ̀ nínú ayé lónìí, ìyẹn ni Bíbélì pè ní “ẹ̀mí tó ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ aláìgbọràn.” (Éfé. 2:2) Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára láti borí àwọn nǹkan tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀, ká má sì jẹ́ kí Èṣù àti ayé burúkú yìí mú ká ṣàìgbọràn. Àmọ́, ó yẹ ká sapá gan-an láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà àtàwọn tó wà nípò àṣẹ. w23.10 6 ¶1

Thursday, October 2

Wáìnì tó dáa lo gbé pa mọ́ títí di àkókò yìí.—Jòh. 2:10.

Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe sọ omi di wáìnì? Ó kọ́ wa pé ó yẹ ká nírẹ̀lẹ̀. Jésù ò fọ́nnu nítorí iṣẹ́ ìyanu yẹn. Kódà, kò sígbà kankan tí Jésù fọ́nnu nípa àwọn nǹkan tó ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ní máa ń jẹ́ kó gbé gbogbo ògo fún Bàbá rẹ̀. (Jòh. 5:​19, 30; 8:28) Táwa náà bá nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, a ò ní máa fọ́nnu nítorí àwọn nǹkan tá à ń gbé ṣe. Kò yẹ ká gbé ògo fún ara wa, kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run tá à ń sìn ló yẹ ká máa yìn torí òun lògo tọ́ sí. (Jer. 9:​23, 24) Ká sòótọ́, kò sí àṣeyọrí tá a lè ṣe láìjẹ́ pé Jèhófà ràn wá lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 1:​26-31) Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, a ò ní fọ́nnu tá a bá ṣe ohun kan láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ọkàn wa máa balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà rí ohun tá a ṣe, ó sì mọyì ẹ̀. (Fi wé Mátíù 6:​2-4; Héb. 13:16) Torí náà, tá a bá fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí wa.—1 Pét. 5:6. w23.04 4 ¶9; 5 ¶11-12

Friday, October 3

Ẹ máa wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.—Fílí. 2:4.

Ẹ̀mí Ọlọ́run darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe ohun tó máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí tá a bá wà nípàdé? Bá a ṣe lè tẹ̀ lé e ni pé ká máa rántí pé àwa nìkan kọ́ ló máa dáhùn nípàdé, ká jẹ́ káwọn ẹlòmíì náà dáhùn. Rò ó wò ná. Tí ìwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ kan bá jọ ń sọ̀rọ̀, ṣé ìwọ nìkan ni wàá máa sọ̀rọ̀ ṣáá àbí wàá fún òun náà láǹfààní láti sọ̀rọ̀? Rárá o, wàá jẹ́ kóun náà sọ̀rọ̀! Lọ́nà kan náà, tá a bá wà nípàdé, dípò ká máa nawọ́ ṣáá, á dáa ká jẹ́ káwọn ẹlòmíì náà dáhùn. Kódà, ọ̀kan lára ohun tá a lè ṣe láti gba àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa níyànjú ni pé, ká fún wọn láǹfààní láti dáhùn kí wọ́n lè sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (1 Kọ́r. 10:24) Jẹ́ kí ìdáhùn ẹ ṣe ṣókí, káwọn ẹlòmíì lè dáhùn. Tí ìdáhùn ẹ bá tiẹ̀ ṣe ṣókí, má sọ kókó tó pọ̀. Tó o bá sọ gbogbo kókó tó wà nínú ìpínrọ̀ náà, àwọn ará ò ní rí nǹkan kan sọ mọ́. w23.04 22-23 ¶11-13

Saturday, October 4

Mò ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíì.—1 Kọ́r. 9:23.

Ó yẹ ká rántí pé ó ṣe pàtàkì ká máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, pàápàá jù lọ ká máa wàásù fún wọn. Ó yẹ ká mọ bá a ṣe máa bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀ tá a bá ń wàásù. Lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, a máa ń pàdé àwọn tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí ìwà wọn àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ sì yàtọ̀ síra. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó sì yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹ̀. Jésù yàn án pé kó jẹ́ “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 11:13) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún un yìí, ó wàásù fáwọn Júù, àwọn Gíríìkì, àwọn ọ̀mọ̀wé, àwọn tálákà, àwọn èèyàn pàtàkì láwùjọ àtàwọn ọba. Kí Pọ́ọ̀lù lè wàásù fún gbogbo àwọn tá a sọ yìí, ó “di ohun gbogbo nítorí gbogbo èèyàn.” (1 Kọ́r. 9:​19-22) Ó kíyè sí ibi tí wọ́n ti wá, àṣà ìbílẹ̀ wọn àtohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ìyẹn jẹ́ kó lè wàásù fún wọn lọ́nà tó wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Táwa náà bá jẹ́ kí ọ̀nà tá à ń gbà wàásù dáa sí i, àá lè wàásù fún onírúurú èèyàn. w23.07 23 ¶11-12

Sunday, October 5

Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, àmọ́ ó yẹ kó máa hùwà jẹ́jẹ́ sí gbogbo èèyàn.—2 Tím. 2:24.

Àwọn tó bá níwà tútù kì í ṣe ojo. Ó gba sùúrù gan-an ká tó lè hùwà jẹ́jẹ́ tí wọ́n bá múnú bí wa. Ìwà tútù jẹ́ ọ̀kan lára “èso ti ẹ̀mí.” (Gál. 5:​22, 23) Nígbà míì, wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìwà tútù” fún ẹṣin kan tó burú, àmọ́ tí wọ́n ti kápá ẹ̀. Fojú inú wo ẹṣin kan tó burú gan-an, àmọ́ tó ti wá ń ṣe jẹ́jẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹṣin náà ti ń ṣe jẹ́jẹ́, ó ṣì lágbára. Báwo làwa náà ṣe lè jẹ́ oníwà tútù, síbẹ̀ ká jẹ́ alágbára? Ká sòótọ́, kì í ṣe ohun tá a lè dá ṣe fúnra wa. Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, ká sì sọ fún un pé kó jẹ́ ká níwà tútù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti fi hàn pé èyí ṣeé ṣe. Ọ̀pọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti fi hàn pé a níwà tútù nígbà táwọn èèyàn ta kò wá tàbí tí wọ́n múnú bí wa, ìyẹn sì ti jẹ́ káwọn èèyàn ní èrò tó tọ́ nípa wa.—2 Tím. 2:​24, 25. w23.09 15 ¶3

Monday, October 6

Mo gbàdúrà nípa rẹ̀, Jèhófà sì fún mi ní ohun tí mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.—1 Sám. 1:27.

Nínú ìran àgbàyanu kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24) tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà lọ́run. Wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń sọ pé òun ló tọ́ sí láti gba “ògo àti ọlá àti agbára.” (Ìfi. 4:​10, 11) Bákan náà, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú káwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ máa yin Jèhófà, kí wọ́n sì máa bọlá fún un. Ọ̀run làwọn áńgẹ́lì yìí ń gbé pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n mọ Jèhófà dáadáa. Wọ́n máa ń rí bí àwọn ànímọ́ Jèhófà ṣe ń hàn nínú gbogbo ohun tó ń ṣe. Àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe yìí ń mú kí wọ́n máa yìn ín. (Jóòbù 38:​4-7) Ó yẹ káwa náà máa yin Jèhófà tá a bá ń gbàdúrà, ká jẹ́ kó mọ ìdí tá a fi nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ àti ìdí tá a fi mọyì àwọn ohun tó ṣe fún wa. Bó o ṣe ń ka Bíbélì tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀, kíyè sí àwọn ànímọ́ Jèhófà tó wù ẹ́. (Jóòbù 37:23; Róòmù 11:33) Lẹ́yìn náà, sọ ìdí táwọn ànímọ́ náà fi wù ẹ́ fún Jèhófà. A tún lè yin Jèhófà torí pé ó ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ àti gbogbo àwọn ará wa kárí ayé.—1 Sám. 2:​1, 2. w23.05 3-4 ¶6-7

Tuesday, October 7

Ẹ máa rìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà.—Kól. 1:10.

Lọ́dún 1919, àwọn èèyàn Ọlọ́run bọ́ lọ́wọ́ Bábílónì Ńlá. Lọ́dún yẹn gan-an ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” dé láti kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ káàbọ̀ sí “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí sílẹ̀. (Mát. 24:​45-47; Àìsá. 35:8) A mọyì àwọn olóòótọ́ tó kọ́kọ́ tún ọ̀nà náà ṣe torí pé ohun tí wọ́n ṣe ti ran àwọn tó ń rin ọ̀nà náà lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. (Òwe 4:18) Ó tún mú kí wọ́n máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Jèhófà ò retí pé kí àwọn èèyàn ẹ̀ ṣe gbogbo àyípadà náà lẹ́ẹ̀kan náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, díẹ̀díẹ̀ ló ń tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà. Ẹ wo bí inú gbogbo wa ṣe máa dùn tó nígbà tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́! Ó yẹ ká máa tún ọ̀nà kan ṣe déédéé kó má bàa bà jẹ́. Láti ọdún 1919 ni a ti ń ṣàtúnṣe “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” kí ọ̀pọ̀ èèyàn lè kúrò nínú Bábílónì Ńlá. w23.05 17 ¶15; 19 ¶16

Wednesday, October 8

Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé.—Héb. 13:5.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí fúnra wọn máa ń dá àwọn arákùnrin tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́kọ̀ọ́, àwọn arákùnrin yìí sì wà nínú onírúurú ìgbìmọ̀ tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń lò. Kódà ní báyìí, àwọn arákùnrin yìí ń fi òótọ́ inú bójú tó ọ̀pọ̀ ojúṣe nínú ètò Ọlọ́run. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn olùrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti gbà yìí ti múra wọn sílẹ̀ láti máa bójú tó àwọn àgùntàn Kristi nìṣó. Nígbà tí èyí tó kẹ́yìn lára àwọn ẹni àmì òróró bá ti lọ sọ́run ní apá ìparí ìpọ́njú ńlá, àwa èèyàn Jèhófà á ṣì máa bá ìjọsìn tòótọ́ lọ láyé. Torí pé Jésù ló ń darí wa, àwa èèyàn Ọlọ́run á ṣì máa sìn ín nìṣó, a ò ní pàdánù ohunkóhun. Òótọ́ ni pé nígbà yẹn, Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù, ìyẹn àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè á ti gbéjà kò wá torí pé wọ́n kórìíra wa. (Ìsík. 38:​18-20) Àmọ́ àkókò tí wọ́n fi máa gbéjà kò wá ò ní pẹ́, kò sì ní dí àwa èèyàn Jèhófà lọ́wọ́ láti máa jọ́sìn ẹ̀. Ó dájú pé ó máa gbà wá sílẹ̀! Nínú ìran kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó jẹ́ ara àgùntàn mìíràn ti Kristi. Áńgẹ́lì kan sọ fún Jòhánù pé “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” yìí wá “látinú ìpọ́njú ńlá.” (Ìfi. 7:​9, 14) Torí náà, ó dá wọn lójú pé Jèhófà máa gbà wọ́n là! w24.02 5-6 ¶13-14

Thursday, October 9

Ẹ má ṣe pa iná ẹ̀mí.—1 Tẹs. 5:19.

Kí ló yẹ ká ṣe kí Ọlọ́run lè fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀? Ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, ká máa ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì wà nínú ètò rẹ̀ tí ẹ̀mí mímọ́ ń darí. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, a máa ní “èso ti ẹ̀mí.” (Gál. 5:​22, 23) Àwọn tí ọkàn wọn mọ́ àtàwọn tí ìwà wọn mọ́ nìkan ni Ọlọ́run máa ń fún ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀. Tá a bá ń ro èròkerò, tá a sì ṣe ohun tá à ń rò, Ọlọ́run ò ní fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ mọ́. (1 Tẹs. 4:​7, 8) Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, kò tún yẹ ká “kó àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ dà nù.” (1 Tẹs. 5:20) “Àsọtẹ́lẹ̀” tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ nípa ẹ̀ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà máa ń bá wa sọ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀. Lára àwọn ọ̀rọ̀ náà ni ọjọ́ Jèhófà tí ò ní pẹ́ dé àti bí àkókò tá a wà yìí ti ṣe pàtàkì tó. Kò yẹ ká máa rò pé ọjọ́ Jèhófà tàbí Amágẹ́dọ́nì ò ní dé lákòókò wa yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé ọjọ́ náà ò ní pẹ́ dé, ká máa hùwà tó dáa, ká sì máa ṣe “iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.”—2 Pét. 3:​11, 12. w23.06 12-13 ¶13-14

Friday, October 10

Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n.—Òwe 9:10.

Kí ló yẹ ká ṣe tí àwòrán ìṣekúṣe bá ṣàdédé jáde lórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà wa? Ṣe ló yẹ ká gbé ojú wa kúrò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ohun tó máa jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ ni tá a bá rántí pé àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ló ṣeyebíye jù lọ. Kódà, àwọn àwòrán kan wà tí kì í ṣe àwòrán ìṣekúṣe tó lè mú ká máa ro èròkerò. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa wo irú àwọn àwòrán bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó lè mú ká ṣàgbèrè nínú ọkàn wa, a ò sì ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 5:​28, 29) Alàgbà kan tó ń jẹ́ David lórílẹ̀-èdè Thailand sọ pé: “Mo máa ń bi ara mi pé, ‘Tí àwòrán kan kì í bá tiẹ̀ ṣe àwòrán ìṣekúṣe, ṣé inú Jèhófà máa dùn sí mi tí mo bá ń wò ó?’ Ìbéèrè tí mo máa ń bi ara mi yìí kì í jẹ́ kí n wo irú àwọn àwòrán bẹ́ẹ̀.” Tá a bá ń bẹ̀rù Jèhófà tọkàntọkàn, a ò ní ṣe ohun tí ò fẹ́. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni “ìbẹ̀rẹ̀” tàbí ìpìlẹ̀ “ọgbọ́n.” w23.06 23 ¶12-13

Saturday, October 11

Ẹ lọ, ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ wọnú yàrá yín tó wà ní inú.—Àìsá. 26:20.

‘Yàrá inú lọ́hùn-ún’ tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ lè jẹ́ àwọn ìjọ wa. Jèhófà ṣèlérí pé tó bá dìgbà ìpọ́njú ńlá, òun máa dáàbò bò wá tá a bá ń jọ́sìn nìṣó pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára báyìí kí ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará wa lè túbọ̀ lágbára láìka ìwà wọn sí. Ó lè jẹ́ ohun tó máa gba ẹ̀mí wa là nìyẹn! Tí “ọjọ́ ńlá Jèhófà” bá dé, nǹkan máa nira fún gbogbo èèyàn. (Sef. 1:​14, 15) Nǹkan sì máa nira fáwa èèyàn Jèhófà náà. Àmọ́ tá a bá ń múra sílẹ̀ báyìí, ọkàn wa máa balẹ̀, àá sì tún lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Á tún jẹ́ ká lè fara da ìṣòro yòówù kó dé bá wa. Táwọn ará wa bá níṣòro, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́, ká fàánú hàn sí wọn, ká sì fún wọn lóhun tí wọ́n nílò. Torí náà, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa báyìí, ó máa rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun, níbi tí kò ti ní sí àjálù àti ìpọ́njú mọ́.—Àìsá. 65:17. w23.07 7 ¶16-17

Sunday, October 12

[Jèhófà] máa fún yín lókun, ó máa sọ yín di alágbára, ó sì máa fẹsẹ̀ yín múlẹ̀ gbọn-in.—1 Pét. 5:10.

Bíbélì sábà máa ń sọ pé àwọn olóòótọ́ èèyàn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà lẹni tó nígbàgbọ́ jù lára wọn máa ń rò pé òun lágbára. Bí àpẹẹrẹ, Ọba Dáfídì sọ pé òun “lágbára bí òkè,” àmọ́ nígbà kan, ó tún sọ pé “jìnnìjìnnì bá mi.” (Sm. 30:7) Sámúsìn ní agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nígbà tí ẹ̀mí Ọlọ́run fún un lókun, síbẹ̀ ó mọ̀ pé láìsí agbára tí Ọlọ́run fún òun, òun ‘ò ní lókun mọ́, òun ò sì ní yàtọ̀ sí gbogbo ọkùnrin yòókù.’ (Oníd. 14:​5, 6; 16:17) Agbára tí Jèhófà fún àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yẹn ló jẹ́ kí wọ́n lókun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà gbà pé òun nílò agbára látọ̀dọ̀ Jèhófà. (2 Kọ́r. 12:​9, 10) Ó ní àìsàn tó ń bá a fínra. (Gál. 4:​13, 14) Nígbà míì, kì í rọrùn fún un láti ṣe ohun tó tọ́. (Róòmù 7:​18, 19) Yàtọ̀ síyẹn, ìdààmú máa ń bá a torí kò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sóun. (2 Kọ́r. 1:​8, 9) Síbẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù jẹ́ aláìlera, ó di alágbára. Lọ́nà wo? Jèhófà ló fún Pọ́ọ̀lù lágbára tó nílò. Òun ló sì fún un lókun. w23.10 12 ¶1-2

Monday, October 13

Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.—1 Sám. 16:7.

Tó bá ń ṣe wá nígbà míì bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló fà wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀. (Jòh. 6:44) Ó ń rí àwọn ànímọ́ dáadáa tá a ní táwa lè má rí, ó sì mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. (2 Kíró. 6:30) Torí náà, ó yẹ ká gbà pé òótọ́ ni Jèhófà sọ nígbà tó sọ pé a ṣeyebíye lójú òun. (1 Jòh. 3:​19, 20) Ká tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn kan lára wa ti ṣe àwọn nǹkan kan tá a ṣì ń kábàámọ̀ ẹ̀ báyìí. (1 Pét. 4:3) Àwọn Kristẹni olóòótọ́ kan náà máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá. Ìwọ ńkọ́, ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò lè dárí jì ẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ torí pé ó ti ṣe àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà kan bẹ́ẹ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gan-an tó bá ń rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sẹ́yìn. (Róòmù 7:24) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀, ó sì ti ṣèrìbọmi. Síbẹ̀, ó sọ pé òun lòun “kéré jù nínú àwọn àpọ́sítélì,” òun sì ni “ẹni àkọ́kọ́” nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.—1 Kọ́r. 15:9; 1 Tím. 1:15. w24.03 27 ¶5-6

Tuesday, October 14

Wọ́n fi ilé Jèhófà sílẹ̀.—2 Kíró. 24:18.

Ohun tá a rí kọ́ nínú ìpinnu tí ò dáa tí Ọba Jèhóáṣì ṣe ni pé ó yẹ ká yan àwọn ọ̀rẹ́ táá jẹ́ ká níwà rere, ìyẹn àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń múnú ẹ̀ dùn. Kì í ṣe àwọn tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ nìkan la lè yàn lọ́rẹ̀ẹ́, a tún lè yan àwọn tó dàgbà jù wá lọ tàbí àwọn tó kéré sí wa. Ẹ má gbàgbé pé Jèhóáṣì kéré gan-an sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Jèhóádà. Tó o bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé àwọn tí mo fẹ́ yàn lọ́rẹ̀ẹ́ yìí máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára? Ṣé wọ́n á jẹ́ kí n máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run? Ṣé wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti òtítọ́ tó ń kọ́ wa? Ṣé wọ́n máa ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run? Ṣé wọ́n máa ń bá mi sòótọ́ ọ̀rọ̀ tí mo bá ṣohun tí ò dáa àbí ńṣe ni wọ́n máa ń sọ pé ohun tí mo ṣe dáa?’ (Òwe 27:​5, 6, 17) Ká sòótọ́, táwọn ọ̀rẹ́ ẹ ò bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò yẹ kó o máa bá wọn rìn. Àmọ́ tó o bá láwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àwọn ọ̀rẹ́ gidi nìyẹn. Má fi wọ́n sílẹ̀ o!—Òwe 13:20. w23.09 9-10 ¶6-7

Wednesday, October 15

Èmi ni Ááfà àti Ómégà.—Ìfi. 1:8.

Ááfà ni lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì, ómégà sì ni lẹ́tà tó kẹ́yìn. Torí náà, nígbà tí Jèhófà sọ pé òun ni “Ááfà àti Ómégà,” ohun tó ń sọ ni pé tóun bá bẹ̀rẹ̀ nǹkan, ó dájú pé òun máa parí ẹ̀. Lẹ́yìn tí Jèhófà dá Ádámù àti Éfà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́n. 1:28) Ìgbà tí Jèhófà sọ̀rọ̀ yìí ni “Ááfà.” Àmọ́ lọ́jọ́ iwájú, nígbà táwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ onígbọràn bá kún ayé, tí wọ́n sì sọ ọ́ di Párádísè ni Jèhófà máa sọ pé “Ómégà.” Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá “ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn” tán, ó sọ ohun tó fi hàn pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ. Ó sọ pé òun máa ṣe ohun tóun ní lọ́kàn fáwa èèyàn àti ayé ní òpin ọjọ́ keje.—Jẹ́n. 2:​1-3. w23.11 5 ¶13-14

Thursday, October 16

Ẹ tún ọ̀nà Jèhófà ṣe! Ẹ la ọ̀nà tó tọ́ gba inú aṣálẹ̀ fún Ọlọ́run wa.—Àìsá. 40:3.

Ó máa gba nǹkan bí oṣù mẹ́rin káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó lè rìnrìn àjò láti Bábílónì pa dà sí Ísírẹ́lì, àmọ́ Jèhófà ṣèlérí pé ohunkóhun tó máa dí wọn lọ́wọ́ tí ò ní jẹ́ kí wọ́n pa dà lòun máa mú kúrò lọ́nà. Àwọn Júù olóòótọ́ yẹn mọ̀ pé àǹfààní táwọn máa rí táwọn bá pa dà sí Ísírẹ́lì ju ohunkóhun táwọn máa fi sílẹ̀ ní Bábílónì lọ. Àǹfààní tó ga jù tí wọ́n máa rí ni pé wọ́n á máa jọ́sìn Jèhófà. Kò sí tẹ́ńpìlì Jèhófà kankan ní Bábílónì. Òfin Mósè sì sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa rúbọ, àmọ́ kò sí pẹpẹ kankan tí wọ́n ti lè rúbọ sí Jèhófà níbẹ̀, kò tún sí àwọn àlùfáà tí wọ́n á máa rú àwọn ẹbọ náà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn abọ̀rìṣà tí ò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà àtàwọn ìlànà ẹ̀ pọ̀ ju àwọn èèyàn Jèhófà lọ. Torí náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù tó bẹ̀rù Ọlọ́run ń retí ìgbà tí wọ́n máa pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, kí wọ́n lè pa dà bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn mímọ́. w23.05 14-15 ¶3-4

Friday, October 17

Ẹ máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.—Éfé. 5:8.

Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ jẹ́ “ọmọ ìmọ́lẹ̀.” Kí nìdí? Ìdí ni pé kò rọrùn láti jẹ́ oníwà mímọ́ nínú ayé tó kún fún ìṣekúṣe yìí. (1 Tẹs. 4:​3-5, 7, 8) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí èrò burúkú tí ayé ń gbé lárugẹ, títí kan àwọn ọgbọ́n orí èèyàn àtàwọn èrò tí ò bá ìlànà Ọlọ́run mu. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀mí mímọ́ tún máa jẹ́ ká ní “oríṣiríṣi ohun rere àti òdodo.” (Éfé. 5:9) Báwo la ṣe lè rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa. Jésù sọ pé Jèhófà “máa fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà tá a bá ń yin Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará nípàdé. (Éfé. 5:​19, 20) Torí náà, ẹ̀mí mímọ́ máa jẹ́ ká láwọn ìwà táá jẹ́ ká máa múnú Ọlọ́run dùn. w24.03 23-24 ¶13-15

Saturday, October 18

Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín.—Lúùkù 11:9.

Ṣé o rò pé ó yẹ kó o túbọ̀ máa ní sùúrù? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, gbàdúrà nípa ẹ̀. Sùúrù wà lára ìwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní. (Gál. 5:​22, 23) Torí náà, a lè gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, kó sì ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní àwọn ìwà yẹn. Tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ tó múnú bí wa, ó yẹ ká “máa béèrè” lọ́wọ́ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ká lè ní sùúrù. (Lúùkù 11:13) A tún lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká máa ní sùúrù bíi tiẹ̀. Lẹ́yìn tá a bá gbàdúrà pé kí Jèhófà ṣe àwọn nǹkan yìí fún wa, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa ní sùúrù lójoojúmọ́. Tá a bá túbọ̀ ń gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ ká máa ní sùúrù, tá a sì ń sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ onísùúrù, kódà tó bá jẹ́ pé a ò kì í ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ohun míì tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o máa ṣàṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tó ní sùúrù ló wà nínú Bíbélì. Tá a bá ṣàṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ yẹn, àá kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, àá sì mọ bó ṣe yẹ káwa náà máa ní sùúrù. w23.08 22-23 ¶10-11

Sunday, October 19

Ẹ rọ àwọ̀n yín sísàlẹ̀ láti kó ẹja.—Lúùkù 5:4.

Jésù fi dá àpọ́sítélì Pétérù lójú pé Jèhófà máa bójú tó o. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó jẹ́ kí Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù rí ẹja pa lọ́nà ìyanu. (Jòh. 21:​4-6) Iṣẹ́ ìyanu yìí jẹ́ kó túbọ̀ dá Pétérù lójú pé Jèhófà máa pèsè àwọn ohun tó nílò. Ó ṣeé ṣe kí Pétérù rántí ohun tí Jésù sọ pé Jèhófà máa pèsè fún àwọn tó bá ń ‘wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mát. 6:33) Torí náà, iṣẹ́ ìwàásù ni Pétérù gbájú mọ́, kì í ṣe iṣẹ́ ẹja pípa. Ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì 33 S.K., ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn. (Ìṣe 2:​14, 37-41) Lẹ́yìn náà, ó tún ran àwọn ará Samáríà àtàwọn tí kì í ṣe Júù lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. (Ìṣe 8:​14-17; 10:​44-48) Ó dájú pé Jèhófà lo Pétérù lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ láti ran onírúurú èèyàn lọ́wọ́, kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni. w23.09 20 ¶1; 23 ¶11

Monday, October 20

Tí ẹ ò bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, a máa gé yín sí wẹ́wẹ́.—Dán. 2:5.

Nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn táwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run, Nebukadinésárì ọba Bábílónì lá àlá kan tó bani lẹ́rù. Nínú àlá náà, ó rí ère ńlá kan. Ó sọ pé òun máa pa gbogbo àwọn amòye òun títí kan Dáníẹ́lì tí wọn ò bá lè sọ àlá náà, kí wọ́n sì túmọ̀ ẹ̀. (Dán. 2:​3-5) Dáníẹ́lì gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ kíákíá, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa kú. Torí náà ó “wọlé, ó sì ní kí ọba yọ̀ǹda àkókò fún òun kóun lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.” (Dán. 2:16) Ẹ ò rí i pé ohun tó ṣe yìí gba ìgboyà àti ìgbàgbọ́! Kò sí àkọsílẹ̀ kankan nínú Bíbélì tó fi hàn pé Dáníẹ́lì ti túmọ̀ àlá rí. Torí náà, ó sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ pé “kí wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run fún àánú nípa àṣírí yìí.” (Dán. 2:18) Jèhófà sì dáhùn àdúrà wọn. Ó ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ láti túmọ̀ àlá Nebukadinésárì, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ kú. w23.08 3 ¶4

Tuesday, October 21

Ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.—Mát. 24:13.

Wo àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń ní sùúrù. Tá a bá ń ní sùúrù, a máa láyọ̀, ọkàn wa sì máa balẹ̀. Torí náà, sùúrù máa ń jẹ́ ká ní ìlera tó jí pépé. Tá a bá ń ní sùúrù fáwọn èèyàn, àárín wa á túbọ̀ gún régé, ìyẹn sì máa jẹ́ káwọn ará ìjọ túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Tẹ́nì kan bá múnú bí wa, àmọ́ tá ò tètè bínú, kò ní jẹ́ kọ́rọ̀ náà dìjà. (Sm. 37:​8, àlàyé ìsàlẹ̀; Òwe 14:29) Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ṣe là ń fara wé Bàbá wa ọ̀run, àá sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ẹ ò rí i pé ìwà tó dáa gan-an ni sùúrù, ó sì ń ṣeni láǹfààní! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti ní sùúrù, tá a bá bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, àá máa ní sùúrù. Bákan náà, bá a ṣe ń ní sùúrù kí ayé tuntun dé, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé “ojú Jèhófà ń ṣọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀, àwọn tó ń dúró de ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.” (Sm. 33:18) Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa fi sùúrù wọ ara wa láṣọ. w23.08 22 ¶7; 25 ¶16-17

Wednesday, October 22

Ìgbàgbọ́ nìkan láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.—Jém. 2:17.

Jémíìsì jẹ́ ká mọ̀ pé ọkùnrin kan lè sọ pé òun nígbàgbọ́, àmọ́ kò ṣe nǹkan tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́. (Jém. 2:​1-5, 9) Jémíìsì tún sọ nípa ẹnì kan tó rí ‘arákùnrin tàbí arábìnrin tí ò láṣọ, tí ò sì ní oúnjẹ,’ àmọ́ tí ò ràn án lọ́wọ́. Tírú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sọ pé òun nígbàgbọ́ àmọ́ tí ò ṣe ohun tó fi hàn bẹ́ẹ̀, irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ò wúlò. (Jém. 2:​14-16) Jémíìsì wá sọ̀rọ̀ nípa Ráhábù, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣe nǹkan tó fi hàn pé a nígbàgbọ́. (Jém. 2:​25, 26) Ráhábù ti gbọ́ nípa Jèhófà, ó sì mọ̀ pé òun ló ń ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́. (Jóṣ. 2:​9-11) Ó ṣe nǹkan tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́. Ó dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì tí wọ́n lọ ṣe amí nígbà tí ẹ̀mí wọn wà nínú ewu. Torí ohun tí obìnrin aláìpé tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì yìí ṣe, a pè é ní olódodo bíi ti Ábúráhámù. Àpẹẹrẹ rere tó fi lélẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká ṣe àwọn iṣẹ́ tó fi hàn pé a nígbàgbọ́. w23.12 5 ¶12-13

Thursday, October 23

Kí ẹ ta gbòǹgbò, kí ẹ sì fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà.—Éfé. 3:17.

Kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ nìkan ló yẹ káwa Kristẹni mọ̀. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tún máa ń jẹ́ kó wù wá láti lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 2:​9, 10) O ò ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa àwọn apá kan nínú Bíbélì táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Bí àpẹẹrẹ, o lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó ṣe fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ nígbà àtijọ́ tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn àtàwọn nǹkan tó ń ṣe fún ìwọ náà báyìí tó jẹ́ kó o mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ. O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ṣètò pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa jọ́sìn òun, kó o wá fi wé báwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń jọ́sìn ẹ̀ lónìí. Yàtọ̀ síyẹn, o tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sí Jésù lára nígbà tó ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ láyé. Inú ẹ máa dùn gan-an tó o bá ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan yìí nínú Watch Tower Publications Index lédè Gẹ̀ẹ́sì tàbí Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, ìgbàgbọ́ ẹ máa lágbára, wàá sì “rí ìmọ̀ Ọlọ́run.”—Òwe 2:​4, 5. w23.10 18-19 ¶3-5

Friday, October 24

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara yín, torí ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.—1 Pét. 4:8.

Ọ̀rọ̀ tí Pétérù lò nínú ẹsẹ yìí, ìyẹn “jinlẹ̀” túmọ̀ sí kéèyàn “na nǹkan.” Apá kejì nínú ẹsẹ yẹn wá sọ ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sáwọn èèyàn. Ó sọ pé ó máa ń bo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará mọ́lẹ̀. Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Téèyàn bá fi ọwọ́ méjèèjì di aṣọ kan mú tó sì fẹ́ fi bo nǹkan, ńṣe lá bẹ̀rẹ̀ sí í nà án títí á fi bo gbogbo ohun tó fẹ́ bò. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká máa fi ìfẹ́ bo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará mọ́lẹ̀, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ẹyọ kan tàbí méjì, àmọ́ “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.” A lè fi béèyàn ṣe ń bo nǹkan wé béèyàn ṣe ń dárí ji àwọn ẹlòmíì. Bí aṣọ ṣe máa ń bo àbùkù ara, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa fi ìfẹ́ bo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ará. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará gan-an, àá dárí jì wọ́n, kódà tó bá ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Kól. 3:13) Tá a bá ń dárí ji àwọn ará, ìyẹn máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, a sì fẹ́ múnú Jèhófà dùn. w23.11 10-12 ¶13-15

Saturday, October 25

Ṣáfánì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á níwájú ọba.—2 Kíró. 34:18.

Nígbà tí Ọba Jòsáyà pé ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26), ó bẹ̀rẹ̀ sí í tún tẹ́ńpìlì Jèhófà ṣe. Bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ náà, wọ́n rí “ìwé Òfin tí Jèhófà fún wọn nípasẹ̀ Mósè.” Nígbà tí wọ́n ka ìwé náà fún ọba, ohun tó gbọ́ mú kó ṣe àtúnṣe lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. (2 Kíró. 34:​14, 19-21) Ṣé ìwọ náà á máa ka Bíbélì lójoojúmọ́? Tó o bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣé ò ń gbádùn ẹ̀? Ṣé o máa ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ẹsẹ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Nígbà tí Jòsáyà pé ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì (39), ó ṣe àṣìṣe ńlá kan tó gba ẹ̀mí ẹ̀. Ó gbára lé ara ẹ̀ dípò kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (2 Kíró. 35:​20-25) Kí nìyẹn kọ́ wa? Kò sí bá a ṣe dàgbà tó tàbí bó ṣe wù kó pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà bọ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Tá a bá máa ṣe bẹ́ẹ̀, ó gba pé ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo pé kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì máa gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní ṣàṣìṣe ńlá tó máa gbẹ̀mí wa bíi ti Jòsáyà, àá sì máa láyọ̀.—Jém. 1:25. w23.09 12-13 ¶15-16

Sunday, October 26

Ọlọ́run dojú ìjà kọ àwọn agbéraga, àmọ́ ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.—Jém. 4:6.

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn obìnrin oníwà rere tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì sìn ín. Wọn kì í ṣe “aláṣejù,” “wọ́n [sì] jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.” (1 Tím. 3:11) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọ̀dọ́bìnrin máa rí àwọn obìnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ní ìjọ wọn, tí wọ́n lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Ẹ̀yin ọ̀dọ́bìnrin, ẹ máa rí àwọn obìnrin rere nínú ìjọ yín tẹ́ ẹ lè fara wé. Ẹ máa kíyè sáwọn ànímọ́ tó dáa tí wọ́n ní. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ wo bẹ́ ẹ ṣe lè láwọn ànímọ́ náà. Ó ṣe pàtàkì pé káwa Kristẹni nírẹ̀lẹ̀. Tí obìnrin kan bá nírẹ̀lẹ̀, ó máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, tí obìnrin kan bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìrẹ̀lẹ̀ máa jẹ́ kó tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà tó sọ pé orí obìnrin ni ọkùnrin. (1 Kọ́r. 11:3) A lè lo ìlànà yìí nínú ìjọ àti nínú ìdílé. w23.12 18-19 ¶3-5

Monday, October 27

Kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn bí ara wọn.—Éfé. 5:28.

Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí ọkọ nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀, kó máa pèsè àwọn nǹkan tó nílò fún un, kó máa ṣìkẹ́ ẹ̀, kó sì máa ṣe ohun táá jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ní àròjinlẹ̀, kó o máa bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin, kó o sì jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá di ọkọ rere. Lẹ́yìn tó o bá láya, ó ṣeé ṣe kó o bímọ. Tó o bá fẹ́ jẹ́ bàbá rere, ẹ̀kọ́ wo lo lè kọ́ lára Jèhófà? (Éfé. 6:4) Jèhófà sọ fún Jésù Ọmọ ẹ̀ ní gbangba pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, òun sì tẹ́wọ́ gbà á. (Mát. 3:17) Torí náà, tó o bá bímọ, rí i dájú pé gbogbo ìgbà lò ń sọ fáwọn ọmọ ẹ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. Tí wọ́n bá ṣe ohun tó dáa, gbóríyìn fún wọn látọkànwá. Àwọn bàbá tó bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà máa ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ báyìí de ojúṣe yìí, bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa fìfẹ́ bójú tó àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìdílé àtàwọn ará ìjọ, kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, o sì mọyì wọn.—Jòh. 15:9. w23.12 28-29 ¶17-18

Tuesday, October 28

[Jèhófà] ló ń mú kí nǹkan lọ bó ṣe yẹ láwọn àkókò rẹ.—Àìsá. 33:6.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá, a máa ń níṣòro, a sì máa ń ṣàìsàn bíi tàwọn yòókù. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń fara da àtakò àti inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn tó kórìíra àwa èèyàn Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń gbà wá tá a bá níṣòro, ó ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́. (Àìsá. 41:10) Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè láyọ̀, ká ṣe ìpinnu tó tọ́, ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí i kódà nígbà tí ìṣòro bá mu wá lómi. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa ní àlàáfíà tí Bíbélì pè ní “àlàáfíà Ọlọ́run.” (Fílí. 4:​6, 7) Àlàáfíà yìí jẹ́ ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní torí pé ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Àlàáfíà yìí “kọjá gbogbo òye,” ó sì ju gbogbo ohun téèyàn lè rò lọ. Ṣé ìgbà kan wà tó o ní ìdààmú ọkàn, àmọ́ tọ́kàn ẹ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ lẹ́yìn tó o gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn? “Àlàáfíà Ọlọ́run” ló mú kíyẹn ṣeé ṣe. w24.01 20 ¶2; 21 ¶4

Wednesday, October 29

Jẹ́ kí n yin Jèhófà; kí gbogbo ohun tó wà nínú mi yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.—Sm. 103:1.

Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń yin orúkọ ẹ̀ tọkàntọkàn. Ọba Dáfídì mọ̀ pé tá a bá ń yin orúkọ Jèhófà, Jèhófà náà là ń yìn yẹn. Tá a bá gbọ́ orúkọ Jèhófà, ó máa ń jẹ́ ká rántí àwọn ìwà rere tó ní àti àwọn ohun rere tó máa ń ṣe. Ó wu Dáfídì pé kó ya orúkọ Bàbá ẹ̀ sí mímọ́, kó sì máa yìn ín. Ó sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn pẹ̀lú “gbogbo ohun tó wà nínú” ẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwọn ọmọ Léfì ló máa ń ṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n bá fẹ́ yin Jèhófà. Síbẹ̀, wọ́n gbà pé kò sí báwọn ṣe lè yin Jèhófà tó bó ṣe yẹ káwọn yìn ín. (Neh. 9:5) Ó dájú pé bí wọ́n ṣe fìrẹ̀lẹ̀ yin Jèhófà, tí wọ́n sì ṣe é tọkàntọkàn máa múnú ẹ̀ dùn gan-an. w24.02 9 ¶6

Thursday, October 30

Níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.—Fílí. 3:16.

Jèhófà ò ní sọ pé aláṣetì ni ẹ́ tọ́wọ́ ẹ ò bá tẹ àfojúsùn tágbára ẹ ò gbé. (2 Kọ́r. 8:12) Kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn nǹkan tí ò jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àfojúsùn ẹ. Máa rántí àwọn nǹkan tó o ti ṣe láṣeyọrí. Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín.” (Héb. 6:10) Torí náà, kò yẹ kíwọ náà gbàgbé iṣẹ́ tó o ti ṣe. Ronú nípa àwọn nǹkan tó o ti ṣe láṣeyọrí. Bí àpẹẹrẹ, o lè ti ṣiṣẹ́ kára láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà, kó o máa sọ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn, o sì ti lè ṣèrìbọmi. Bó o ṣe tẹ̀ síwájú, tọ́wọ́ ẹ sì tẹ àwọn àfojúsùn ẹ láwọn ìgbà kan sẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ kó o máa tẹ̀ síwájú kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ní. Inú ẹ máa dùn nígbà tí Jèhófà bá jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àfojúsùn ẹ. Bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àfojúsùn ẹ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, jẹ́ kí inú ẹ máa dùn bó o ṣe ń rí i tí Jèhófà ń ràn ẹ́ lọ́wọ́, tó sì ń bù kún ẹ. (2 Kọ́r. 4:7) Torí náà tó ò bá jẹ́ kó sú ẹ, Jèhófà máa bù kún ẹ lọ́pọ̀lọpọ̀.—Gál. 6:9. w23.05 31 ¶16-18

Friday, October 31

Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún yín, torí pé ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi, ẹ sì ti gbà gbọ́ pé mo wá bí aṣojú Ọlọ́run.—Jòh. 16:27.

Jèhófà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ẹ̀ mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, inú òun sì ń dùn sí wọn. Nínú Bíbélì, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ fún Jésù pé àyànfẹ́ òun ni, òun sì ti tẹ́wọ́ gbà á. (Mát. 3:17; 17:5) Ṣé ìwọ náà fẹ́ kí Jèhófà sọ fún ẹ pé inú òun dùn sí ẹ? Lónìí, Jèhófà kì í bá wa sọ̀rọ̀ tààràtà látọ̀run, àmọ́ ó máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀ láti bá wa sọ̀rọ̀. Síbẹ̀ a lè “gbọ́” ohùn Jèhófà tó ń sọ fún wa pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. Lọ́nà wo? Tá a bá ń ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere. Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀ délẹ̀délẹ̀. Torí náà, tá a bá ń kà nípa bí Jésù ṣe gbóríyìn fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláìpé tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́, ṣe ló máa dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fáwa náà pé inú òun dùn sí wa. (Joh. 15:​9, 15) Tá a bá níṣòro, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Jèhófà ń bínú sí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìṣòro máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó àti bá a ṣe gbẹ́kẹ̀ lé e tó.—Jém. 1:12. w24.03 28 ¶10-11

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́