ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 3/1 ojú ìwé 10-13
  • Idi Ọpẹ́ Mi Ti Pọ Lọpọlọpọ Tó!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Idi Ọpẹ́ Mi Ti Pọ Lọpọlọpọ Tó!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iṣẹ Ti Mo Kọ́ Ni Ile Ẹkọ
  • Awọn Apejọpọ Agbaye
  • Kikowọnu Òtú Aṣaaju-ọna
  • Ajọ Agberohinjade Ṣeranlọwọ
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti 1998
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Wíwá Ìjọba náà Lákọ̀ọ́kọ́ Ló Jẹ́ Kí Ìgbésí Ayé Wa Kún fún Ìfọ̀kànbalẹ̀ àti Ayọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 3/1 ojú ìwé 10-13

Idi Ọpẹ́ Mi Ti Pọ Lọpọlọpọ Tó!

GẸGẸ BI LOTTIE HALL TI SỌ Ọ

O ṢẸLẸ loju ọna ni igba ti a nbọ lati Calcutta, India, lọ si Rangoon Burma ni 1963. Ni kete lẹhin fifi Calcutta silẹ nipasẹ ọkọ̀ ofuurufu, ọkan lara awọn arakunrin ṣakiyesi epo ti ńjò sara ọkan lara awọn apá ọkọ̀ ofuurufu naa. Nigba ti a sọ fun wọn nipa rẹ̀, ẹgbẹ awọn awakọ naa kede pe a o balẹ ni pàjáwìrì. Ọkọ̀ ofuurufu naa nilati kọkọ tú ọpọlọpọ epo ọkọ jade lati mu ki o ṣeeṣe lati balẹ̀. Olubojuto awọn èrò kigbe jade pe, “Bi ẹ ba fẹ lati gbadura, ẹ gba a nisinsinyi o!” A gbadura nitootọ pe bi o ba jẹ ifẹ-inu Jehofa, ki a balẹ laisewu, o sì ṣẹlẹ bẹẹ. Nitootọ a ni ohun kan lati kun fun ọpẹ fun!

BẸẸNI, mo tun ni ohun pupọ miiran lati kun fun ọpẹ́ fun. Ni ẹni ọdun 79, mo ṣi ni ilera ati okun de aye kan, eyi ti mo nlo ninu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun. Ju bẹẹ lọ, ni afikun si awọn ibukun wọnni ti gbogbo awọn eniyan Jehofa ńrí, mo ti ni ọpọlọpọ iriri ti o tayọ. Lapapọ o ti jẹ ipin ṣiṣeyebiye fun mi lati ṣiṣẹsin Jehofa fun ohun ti o tó 60 ọdun, ohun ti o si ju ilaji akoko yẹn ni mo ti fi jẹ ojiṣẹ alakooko kikun, tabi aṣaaju-ọna.

Gbogbo rẹ̀ bẹrẹ pẹlu baba mi nigba ti a ngbe ni Carbondale, Illinois. Oun darapọ mọ ẹka isin Awọn Ọmọlẹhin Kristi o sì nifẹẹ sí didi ojiṣẹ kan. Bi o ti wu ki o ri, iriri rẹ̀ pẹlu awọn ile ẹkọ giga meji nipa Bibeli bà á ninu jẹ́, nitori oun ni ero tirẹ nipa Mẹtalọkan, aileku ọkan, ati ijẹrora ayeraye.

Asẹhinwa asẹhinbọ, o ri itẹlọrun pẹlu otitọ Bibeli ti Akẹkọọ Bibeli kan ti o npin iwe irohin isin kiri ni 1924 mu wa fun un, nigba ti mo jẹ kiki ẹni ọdun mejila. Inu baba mi dun lati mọ pe awọn miiran nbẹ ti wọn nimọlara gẹgẹ bi oun ti ṣe, pe Mẹtalọkan, iná ọrun apaadi, ati aileku ọkan ẹda eniyan jẹ awọn ẹkọ èké. Laipẹ idile wa npade pọ deedee pẹlu awọn Akẹkọọ Bibeli, gẹgẹ bi a ti npe awọn Ẹlẹrii Jehofa nigba naa. Kikẹkọọ otitọ nipa Jehofa ati Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ ohun kan ti o mu mi kun fun ọpẹ nitootọ.

Bi o ti wu ki o ri, laipẹ, ajalu ṣẹlẹ. Ọkunrin naa ti o mu awọn otitọ yii wa fun baba mi di alábòsí ati oniwapalapala nikẹhin. O mu ki baba mi kọsẹ̀, ayafi mama ati emi. Nisinsinyi ti mo jẹ ẹni ọdun 15, emi ni o dagba ju laaarin awọn ọmọ mẹfa, mo sì rọ̀ mọ́ otitọ pẹlu mama mi.

Nigba ẹ̀rùn 1927, a kede rẹ̀ pe apejọpọ nla ti awọn Akẹkọọ Bibeli ni a o ṣe ni Toronto, Canada. Baba mi sọ pe apa oun kò lè ká a lati lọ, ṣugbọn Iya mi jẹ onipinnu obinrin. O bẹrẹ sii ta awọn oniruuru nnkan eelo ile, nigba ti o sì maa fi di akoko apejọpọ, oun ti ṣakojọ dollar mẹjọ. Pẹlu iye yẹn oun ati emi bẹrẹ sii wọ ọkọ̀ àjáwọ̀ lọ si Toronto, ti o jinna to ẹgbẹrun kan ibusọ. O gba ọjọ marun-un ati ọkọ̀ wiwọ 37 ki a to de ibẹ nikẹhin, a de ibẹ ni ọjọ kan ṣaaju ki apejọpọ naa to bẹrẹ. Nitori pe owó wa ti fẹrẹẹ tan, a beere a sì ri ile àwọ̀sùn ọ̀fẹ́ gbà. Nigba ti Arakunrin A. H. Macmillan gbọ nipa irin ajo wa, o kọ irohin rẹ̀ fun iwe irohin apejọpọ labẹ akọle naa “Igbega Owó Irinna Ọkọ Oju Irin Eyikeyii Ko Yọ Awọn Akẹkọọ Bibeli Wọnyi Lẹnu.”

Iya fi to Baba mi leti nipasẹ kaadi ifirohin ranṣẹ. Nitori naa, ni ikẹhin, oun pinnu lati wa lọnakọna o si de pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ sí akoko asọye fun gbogbo eniyan ni ọjọ ti o gbẹhin apejọpọ naa. Nisinsinyi awa kò nilati maa wọ ọkọ àjáwọ̀ pada lọ si ile wa. Iru apejọpọ wo ni o jẹ! Bawo ni mo ti kun fun ọpẹ to pe o ti ṣeeṣe fun wa lati lọ sibẹ. Bawo ni mo sì ti kun fun imoore to pe o ran baba mi lọwọ lati jèrè ìwàdéédéé tẹmi rẹ̀ pada!

Fun ọpọlọpọ ọdun nigba ti a ba bi mi leere ohun ti isin mi jẹ, emi yoo dahun pe “IBSA,” awọn lẹta ti wọn duro fun International Bible Students Association. Ṣugbọn emi maa nnimọlara ailayọ nigba gbogbo pẹlu orukọ yẹn. Nitori naa, mo kun fun imoore pe mo wà ni apejọpọ 1931 naa ni Columbus, Ohio, nigba ti a gba orukọ titun naa Ẹlẹrii Jehofa.

Iṣẹ Ti Mo Kọ́ Ni Ile Ẹkọ

Lara ọpọ ibukun ti o ti mu ki igbesi aye mi ládùn ni awọn wọnni ti o sopọ mọ́ orin. Mo kundun orin gan-an mo sì ti kẹkọọ lati tẹ piano lati ibẹrẹ wa. Fun ọpọlọpọ ọdun mo ni anfaani fifi ẹrọ orin gbe orin ti ijọ nkọ lẹ́sẹ̀. Ṣaaju ki Watch Tower Society to bẹrẹ sii ṣe ìgbàsílẹ̀ awọn orin Ijọba, arakunrin ojihin iṣẹ Ọlọrun kan ti o nṣiṣẹsin ni Papua New Guinea sọ fun mi lẹẹkan ri pe ki nṣe ìgbàsílẹ̀ ohùn awọn orin wa melookan ki awọn ará Papua baa mọ̀ bi a ti nkọ wọn. Iyẹn jẹ ohun kan ti mo gbadun ni ṣiṣe nitootọ gidi.

Bi o ti wu ki o ri, ohun eelo ti mo fẹran julọ ni clarinet. Mo gbadun lilo o ninu àwùjọ olorin ile ẹkọ giga. Olukọ ile ẹkọ giga naa ni itẹlọrun pẹlu bi mo ṣe ngbe ohùn orin jade debi pe oun sọ fun mi pe ki ntun bá ẹgbẹ́ oṣere awọn ọkunrin ṣere. Ni awọn ọjọ wọnni ko si obinrin kankan ti o tii ṣere ninu ẹgbẹ́ oṣere awọn ọkunrin ri, nitori naa nigba ti awọn mẹmba ẹgbẹ oṣere naa gbọ́ ohun ti olukọ agba naa ti gbèrò, wọn ṣeto lati da iṣẹ silẹ. Wọn rò ó daadaa nigba ti a fun wọn ni ikilọ pe bi wọn ba da iṣẹ silẹ, a o le wọn lọ. Aṣa atọwọdọwọ miiran ni a tun fòpinsí nigba ti a beere pe ki nyan pẹlu ẹgbẹ́ awọn olorin ninu ìréde kan ṣúlẹ̀ ọjọ. Iwe irohin kà á si ohun arufẹsoke o sì rohin rẹ̀ pẹlu akọle gàdàgbà: “Ọdọmọbinrin Olorin laaarin Agbami awọn Ọkunrin.”

Asẹhinwa asẹhinbọ, a fi ọ̀rọ̀ wa mi lẹnu wo fun ipo olukọ ninu kikọni ní orin. Bi o ti wu ki o ri, ni rironu nipa gbogbo ariyanjiyan ti o le dide bi emi yoo ba maa kọ́ni ni orin, iru bii sisọ fun mi lati kọni tabi gbé ohùn orin onisin ati onifẹẹ orilẹ-ede jade, mo pinnu lati lepa ohun miiran a sì yàn mi lati kọ́ni ni ẹkọ itan ayé. Ṣugbọn fun ọpọ ọdun lẹhin naa, iyipada yẹn ko di mi lọwọ ninu fifi clarinet mi kọrin ninu awọn awujọ olorin apejọpọ ni ọpọlọpọ ilẹ̀ gẹgẹ bi mo ti nririn ajo lọ si apejọpọ agbaye ti awọn Ẹlẹrii Jehofa.

Laipẹ, mo di olukọni ní ìtàn aye ní ile ẹkọ giga titobi kan ni ìgbèríko Detroit, ati nitori eyi, olori ile ẹkọ naa sọ fun mi nigbakanri lati damọran ọkan lara oniruuru awọn iwe ẹkọ titun fun lilo. Ni ṣiṣatunyẹwo iwọnyi, mo daamu nitori otitọ naa pe nigba ti iwe ẹkọ ti lọwọlọwọ mẹnukan orukọ Jehofa ni igba mẹjọ, awọn titun fi Ọlọrun awọn Heberu silẹ laini orukọ, bi o tilẹ jẹ pe wọn sọ orukọ ọpọlọpọ awọn ọlọrun awọn orilẹ-ede abọriṣa, iru bi Ra, Moleki, Seọs, ati Jupita. Nigba ti ọkunrin ontaja kan wa, mo beere lọwọ rẹ̀ idi ti a ko fi mẹnukan Jehofa ninu iwe ẹkọ rẹ̀, oun sì wipe: “Bẹẹkọ, awa ki yoo fi orukọ yẹn sinu iwe ẹkọ wa nitori awọn Ẹlẹrii Jehofa.” Nitori naa mo sọ fun un pe: “O dara! Nigba naa emi ki yoo damọran iwe ẹkọ tìrẹ.” Oun fi agbara sọ iwe naa sinu àpò o sì yara jade kuro ni ẹnu ilẹkun ni kiakia.

Lẹhin naa, mo rohin pada fun olori ile ẹkọ naa pe a ko nilo iwe ẹkọ titun niti gidi mo sì fun un ni awọn ìdí pataki melookan. Oun gbà pẹlu mi. Inu gbogbo awọn eniyan ni o dùn pẹlu ipinnu yii nigba ti, kiki lẹhin awọn oṣu diẹ sii, a pinnu rẹ̀ lati yọ idanilẹkọọ nipa itan aye kuro ninu itolẹsẹẹsẹ awọn ẹkọ ti a nkọ ninu awọn ile ẹkọ giga. Idanilẹkọọ titun kan, ti a npe ni ẹkọ nipa ẹgbẹ oun ọgba (social studies) ni o rọpo rẹ̀ jalẹjalẹ eto-igbekalẹ ile ẹkọ onipele mẹrinla naa. Bi o ba jẹ pe gbogbo akẹkọọ ati olukọ ti ra awọn iwe itan titun, àdánù wo ni iyẹn iba ti muwa!

Mo ni ọpọlọpọ awọn iriri gbigbadunmọni ninu kikọni ni ile ẹkọ mo sì jẹ amuni tẹle ilana pẹkipẹki. Eyi mu mi ni ọpọlọpọ awọn ọ̀rẹ́ jalẹ igbesi aye. Mo tun ni ọpọlọpọ anfaani lati ṣe ijẹrii alaijẹ bi àṣà. Ṣugbọn ni asẹhinwa asẹhinbọ akoko ati ipo awọn nnkan mu mi wọnu iṣẹ isin alakooko kikun.

Awọn Apejọpọ Agbaye

Lẹhin kikọni ninu ile ẹkọ fun 20 ọdun, oju mi bẹrẹ sii padanu iriran kedere. Siwaju sii, awọn òbí mi nimọlara pe wọn nilo mi, nitori naa baba mi sọ pe ki nwa si ile, ni sisọ pe iṣẹ ikọnilẹkọọ ti o ṣe pataki ju wa lati ṣe, Jehofa yoo sì ri sii pe ebi kò pa mi. Mo fi iṣẹ olukọ silẹ ni 1955, lára awọn ibukun mi akọkọ lẹhin naa ni lilọ si ọ̀wọ́ awọn apejọpọ “Ijọba Alayọ Iṣẹgun” ni Europe. Bawo ni mo ti kun fun ọpẹ́ to lati wà pẹlu awọn arakunrin wa ni Europe, ti ọpọlọpọ ninu wọn ti la ijiya pupọ kọja laaarin akoko ogun agbaye keji! Ni pataki ni o jẹ ibukun lati wa laaarin 107,000 ti wọn kún fọ́fọ́ si Zeppelinwiese, tabi Pápá-oko Zeppelin, ni Nuremberg, nibi ti Hitler ti ṣeto lati yan fun ijagunmolu rẹ̀ lẹhin Ogun Agbaye Keji.

Iyẹn wulẹ jẹ akọkọ ninu ọpọlọpọ ìrìn àjò yika aye ti mo ti ni anfaani lati rin. Ni 1963 emi ati iya mi wà lara 583 awọn olupejọ lati ririn ajo yika aye lọ si Awọn Apejọ “Ihinrere Ainipẹkun.” Irin ajo yẹn mu wa lọ lati New York si Europe, lẹhin naa lọ si Asia ati awọn erekuṣu ni Pacific kí á tó wá pari rẹ̀ si Pasadena, California. Ni akoko irin ajo yẹn ni a ni iriri ti ndayafoni naa ti a ṣapejuwe ninu inasẹ ibẹrẹ. Lẹhin naa irin ajo ibẹwo gbe wa lọ si awọn apejọpọ ni Guusu America, Guusu Pacific, ati Africa. Nitootọ, awọn irin ajo wọnyi mu igbesi-aye mi sunwọn sii, ati bi o ti ṣeeṣe fun mi lati lò ohun eelo orin ninu ẹgbẹ olorin apejọpọ ni ibi pupọ lara iwọnyi tun jẹ afikun anfaani fun ololufẹ orin kan.

Kikowọnu Òtú Aṣaaju-ọna

Ni 1955, lẹhin pipada lati Europe, mo darapọ mọ iya mi ninu iṣẹ aṣaaju-ọna fun ọdun kan, lẹhin naa Society sọ fun mi lati ṣiṣẹ pẹlu ijọ kekere kan ni Apalachicola ni iwọ oorun Florida. Fun ọdun meje emi ati arabinrin miiran ṣeranwọ ninu iṣẹ nibẹ, laipẹ ijọ naa sì lè kọ́ Gbọngan Ijọba kan lati fi aaye gba ìbísí naa. Itẹsiwaju nbaa lọ, ati laipẹ ijọ miiran ni a da silẹ ni Port Saint Joe. Mo lo ọdun mọkanla ni ṣiṣiṣẹ pẹlu ijọ mẹtẹẹta ni iha iwọ-oorun Florida.

Nigba kan alaboojuto ayika sọ fun mi lati wa aaye fun apejọ ayika. O ṣeeṣe fun mi lati ri lilo Ile Ajọdun Ọgọrun-un Ọdun ti o kun fun iyì ni Port Saint Joe gbà fun kìkì $10. Ṣugbọn a tun nilo ile ijẹun kan, a sì ronu lilo ile ijẹun ile-ẹkọ kan. Bi o ti wu ki o ri, mo rii pe oluṣabojuto awọn ile ẹkọ ṣatako, o sì sọ pe emi yoo nilati fi oju kan ajọ igbimọ ile-ẹkọ. Olori ilu naa wa sibi ipade yẹn pẹlu, bi o ti jẹ pe oun fẹ ki a lo ile ijẹun naa. Nigba ti o beere awọn idi ti wọn kò fi fẹ lati fun wa ni ile ijẹun naa, olori ajọ igbimọ ile-ẹkọ sọ pe kò tii si awujọ onisin ti o lo awọn ile ti ile-ẹkọ nlo rí. Olori ilu naa yiju si mi fun èsì. Tóò, mo ni ọpọlọpọ iwe ilewọ ti o nfihan pe a ti lo awọn ile ti ile-ẹkọ nlo rí fun awọn ipade wa ni awọn ilu miiran, lẹhin naa mo sì tọkasi Iṣe 19:9, eyi ti o sọ pe apọsteli Pọọlu waasu ninu gbọngan ile-ẹkọ. Iyẹn yanju ọ̀ràn. Ajọ-igbimọ naa fohunṣọkan pẹlu olori ilu naa lati jẹ ki a lo ile ijẹun naa—fun $36.

Nigba ti mo jẹ ẹni ọdun 13, ni ọjọ-ori ti a baptisi mi, mo gbadura pe: “Óò Ọlọrun, ṣaa ti jẹ ki nmu ẹni kan wa sinu otitọ.” Adura yẹn ni o ngba nisinsinyi lọpọlọpọ igba leralera gẹgẹ bi a ti bukun mi ninu riran ọpọlọpọ eniyan lọwọ lati mu iduro wọn fun Jehofa ati Ijọba rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, leralera ṣaaju ki akẹkọọ Bibeli kan to de ori iyasimimọ ati baptism, wọn a ti pin mi si ijọ miiran. Sibẹ, mo ni anfaani gbígbìn ati bíbominrin, ọpọlọpọ awọn akẹkọọ wọnyi sì ti jasi ọ̀rẹ́ mi jalẹ igbesi-aye. Ṣiṣajọpin ninu iru awọn igbokegbodo amesojade bẹẹ fun mi ni ìdí lati kun fun ọpẹ nitootọ.

Ajọ Agberohinjade Ṣeranlọwọ

Nigba ti ajọ agberohinjade ni ibi pupọ ti rohin igbokegbodo awọn Ẹlẹrii Jehofa lọpọlọpọ ìgbà lọna ti ko dara, inu mi dun lati sọ pe ajọ agberohinjade ni De Land, Florida—nibi ti mo ti nṣiṣẹsin nisinsinyi—ti ran mi lọwọ lati jẹrii. Fun apẹẹrẹ, nigba ti mo wà lẹnu ọkan lara awọn irin ajo lọ si apejọpọ agbaye wọnni, emi ati iya mi fi irohin gigun ranṣẹ si ile iṣẹ iwe irohin adugbo, iwọnyi ni a sì tẹjade, papọ pẹlu awọn aworan laisi iṣoro. Irohin naa jẹ́ lọ́nà alaworan irin-ajo pẹlu alaye, ṣugbọn a maa ngbiyanju lò wọn nigbagbogbo lati jẹrii nipa orukọ ati Ijọba Jehofa.

Ohun kan naa ni o ti jẹ otitọ niti ijẹrii òpópónà. Mo ni igun òpópónà kan nibi ti mo gbé àga inaju lori koriko meji si, emi yoo jokoo lori ọ̀kan emi yoo sì pàtẹ awọn iwe ikẹkọọ wa sori ekeji. Nigba kan ri, ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ti o gba ilaji oju-iwe pẹlu aworan farahan ninu iwe irohin adugbo kan labẹ akori naa: “Lottie Ara Deland Nba Iṣẹ Awọn Òbí Rẹ̀ Lọ Gẹgẹ Bi Ẹlẹrii.” Lẹnu aipẹ yii, ni 1987, iwe irohin miiran ni ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ti o gba ilaji oju-iwe ti o ni aworan gàdàgbà alawọ mèremère labẹ akori naa: “Lottie Hall Ni Àyè Tirẹ̀ Funraarẹ Ti O Yàn fun Kristi.” Ni ọdun ti o tẹle e iwe irohin miiran ni aworan mi ni oju-iwe iwaju pẹlu iru awọn ọ̀rọ̀ akiyesi bii, “O máa ńwà nibẹ ṣáá ni” ati, “Ni jijokoo lori àga inaju lori koriko kan, olukọ ile ẹkọ ti o ti fẹhinti naa ńlo àyè igun òpópónà rẹ̀ lati ṣe iṣẹ́ ojihin iṣẹ Ọlọrun ti Ẹlẹrii Jehofa.” Pẹlupẹlu, nigba mẹrin ile iṣẹ tẹlifiṣọn agbegbe ti fi awọn aworan hàn nipa iṣẹ ijẹrii mi. Mo nbaa lọ lati ṣajọpin de iwọn ti o ni aala ninu gbogbo apa iha iṣẹ ojiṣẹ Ijọba naa: iwaasu ile de ile, ipadabẹwo, ati ikẹkọọ Bibeli inu ile. Bi o ti wu ki o ri, nitori ọjọ ori ti o nga sii ati ailera ti ara, mo nlo akoko pupọ ninu iṣẹ òpópónà nisinsinyi.

Ni wiwẹhin wò mo gbọdọ sọ pe mo ni ọpọlọpọ idi lati kun fun ọpẹ. Ni afikun si awọn ibukun wọnni ti o wọpọ fun awọn eniyan Jehofa, mo ti ni anfaani lilo agbara idari lori ọpọlọpọ awọn ọ̀dọ́ gẹgẹ bi olukọ ile ẹkọ kan; mo ti ni ayọ ti lilọ si ọpọlọpọ apejọpọ yika aye; mo ti ṣe iṣẹ́ ojiṣẹ aṣaaju-ọna ti o mesojade julọ; a sì ti bukun mi pẹlu ni isopọ pẹlu orin. Ju bẹẹ lọ, ijẹrii ti mo lè ṣe nipasẹ awujọ agberohinjade wà nibẹ. Nitootọ, mo lè sọ pẹlu Dafidi onisaamu naa pe: “Emi yoo fi orin yin orukọ Ọlọrun, emi yoo sì fi ọpẹ́ gbe orukọ rẹ̀ ga.”—Saamu 69:30.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́